Surah 'Abasa in Yoruba: translation and audio
Surah 80 · عبس · He Frowned · 42 verses
Surah 'Abasa verse by verse: the Arabic with a recitation you can repeat, the transliteration, and the Yoruba translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni. For the meaning of every word, see Surah 'Abasa word by word in English.
Verse 1
عَبَسَ وَتَوَلَّىٰٓ
Transliteration ʿabasa watawallā
Yoruba Ó fajú ro, ó sì pẹ̀yìndà1
Verse 2
أَن جَآءَهُ ٱلْأَعْمَىٰ
Transliteration an jāahu l-aʿmā
Yoruba nítorí pé afọ́jú wá bá a.
Verse 3
وَمَا يُدْرِيكَ لَعَلَّهُۥ يَزَّكَّىٰٓ
Transliteration wamā yud'rīka laʿallahu yazzakkā
Yoruba Kí sì l’ó máa fi mọ̀ ọ́ pé ó ṣeé ṣe kí ó ṣàfọ̀mọ́ (ara rẹ̀ kúrò nínú àìgbàgbọ́)
Verse 4
أَوْ يَذَّكَّرُ فَتَنفَعَهُ ٱلذِّكْرَىٰٓ
Transliteration aw yadhakkaru fatanfaʿahu l-dhik'rā
Yoruba tàbí kí ó gbọ́ ìrántí, kí ìrántí náà sì ṣe é ní àǹfààní?
Verse 5
أَمَّا مَنِ ٱسْتَغْنَىٰ
Transliteration ammā mani is'taghnā
Yoruba Ní ti ẹni tí ó ka ara rẹ̀ kún ọlọ́rọ̀,
Verse 6
فَأَنتَ لَهُۥ تَصَدَّىٰ
Transliteration fa-anta lahu taṣaddā
Yoruba òun ni ìwọ tẹ́tí sí.
Verse 7
وَمَا عَلَيْكَ أَلَّا يَزَّكَّىٰ
Transliteration wamā ʿalayka allā yazzakkā
Yoruba Kò sì sí ẹ̀ṣẹ̀ fún ọ bí kò bá ṣe àfọ̀mọ́ (ara rẹ̀ kúrò nínú àìgbàgbọ́).
Verse 8
وَأَمَّا مَن جَآءَكَ يَسْعَىٰ
Transliteration wa-ammā man jāaka yasʿā
Yoruba Ní ti ẹni tí ó sì wá bá ọ, tó ń yára gágá (sí ìrántí, ìyẹn afọ́jú),
Verse 9
وَهُوَ يَخْشَىٰ
Transliteration wahuwa yakhshā
Yoruba tí ó sì ń páyà (Allāhu),
Verse 10
فَأَنتَ عَنْهُ تَلَهَّىٰ
Transliteration fa-anta ʿanhu talahhā
Yoruba ìwọ kò sì kọbi ara sí i.
Verse 11
كَلَّآ إِنَّهَا تَذْكِرَةٌ
Transliteration kallā innahā tadhkiratun
Yoruba Rárá (kò tọ́ bẹ́ẹ̀). Dájúdájú al-Ƙur’ān ni ìrántí.
Verse 12
فَمَن شَآءَ ذَكَرَهُۥ
Transliteration faman shāa dhakarahu
Yoruba Nítorí náà, ẹni tí ó bá fẹ́ kí ó rántí rẹ̀.
Verse 13
فِى صُحُفٍ مُّكَرَّمَةٍ
Transliteration fī ṣuḥufin mukarramatin
Yoruba (Al-Ƙur’ān) wà nínú àwọn tàkádà alápọ̀n-ọ́nlé,
Verse 14
مَّرْفُوعَةٍ مُّطَهَّرَةٍۭ
Transliteration marfūʿatin muṭahharatin
Yoruba A gbé e ga, A sì ṣe é ní mímọ́
Verse 15
بِأَيْدِى سَفَرَةٍ
Transliteration bi-aydī safaratin
Yoruba ní ọwọ́ àwọn òǹkọtíà (ìyẹn, àwọn mọlāika),
Verse 16
كِرَامٍۭ بَرَرَةٍ
Transliteration kirāmin bararatin
Yoruba àwọn alápọ̀n-ọ́nlé, àwọn ẹni rere.
Verse 17
قُتِلَ ٱلْإِنسَـٰنُ مَآ أَكْفَرَهُۥ
Transliteration qutila l-insānu mā akfarahu
Yoruba Wọ́n ti fi ènìyàn gégùn-ún (nípa) bí ó ṣe jẹ́ aláìmoore jùlọ!
Verse 18
مِنْ أَىِّ شَىْءٍ خَلَقَهُۥ
Transliteration min ayyi shayin khalaqahu
Yoruba Kí sì ni Allāhu fi ṣẹ̀dá rẹ̀?
Verse 19
مِن نُّطْفَةٍ خَلَقَهُۥ فَقَدَّرَهُۥ
Transliteration min nuṭ'fatin khalaqahu faqaddarahu
Yoruba Nínú àtọ̀ l’Ó ti ṣẹ̀dá rẹ̀. Ó sì pèbùbù (ẹ̀yà-ara) rẹ̀.
Verse 20
ثُمَّ ٱلسَّبِيلَ يَسَّرَهُۥ
Transliteration thumma l-sabīla yassarahu
Yoruba Lẹ́yìn náà, Ó ṣe ọ̀nà àtiwáyé ní ìrọ̀rùn fún un.
Verse 21
ثُمَّ أَمَاتَهُۥ فَأَقْبَرَهُۥ
Transliteration thumma amātahu fa-aqbarahu
Yoruba Lẹ́yìn náà, Ó máa pa á. Ó sì máa fi sínú sàréè.
Verse 22
ثُمَّ إِذَا شَآءَ أَنشَرَهُۥ
Transliteration thumma idhā shāa ansharahu
Yoruba Lẹ́yìn náà, nígbà tí Allāhu bá fẹ́, Ó máa gbé e dìde.
Verse 23
كَلَّا لَمَّا يَقْضِ مَآ أَمَرَهُۥ
Transliteration kallā lammā yaqḍi mā amarahu
Yoruba Rárá o! Ènìyàn kò tí ì ṣe n̄ǹkan tí Allāhu pa láṣẹ fún un.
Verse 24
فَلْيَنظُرِ ٱلْإِنسَـٰنُ إِلَىٰ طَعَامِهِۦٓ
Transliteration falyanẓuri l-insānu ilā ṭaʿāmihi
Yoruba Nítorí náà, kí ènìyàn wòye sí oúnjẹ rẹ̀.
Verse 25
أَنَّا صَبَبْنَا ٱلْمَآءَ صَبًّا
Transliteration annā ṣababnā l-māa ṣabban
Yoruba Dájúdájú Àwa ń rọ òjò ní púpọ̀.
Verse 26
ثُمَّ شَقَقْنَا ٱلْأَرْضَ شَقًّا
Transliteration thumma shaqaqnā l-arḍa shaqqan
Yoruba Lẹ́yìn náà, A mú ilẹ̀ sán kànkàn.
Verse 27
فَأَنۢبَتْنَا فِيهَا حَبًّا
Transliteration fa-anbatnā fīhā ḥabban
Yoruba A sì mú kóró èso hù jáde láti inú rẹ̀;
Verse 28
وَعِنَبًا وَقَضْبًا
Transliteration waʿinaban waqaḍban
Yoruba àti èso àjàrà àti kànnáfùrù,
Verse 29
وَزَيْتُونًا وَنَخْلًا
Transliteration wazaytūnan wanakhlan
Yoruba àti igi òróró Zaetūn àti dàbínù,
Verse 30
وَحَدَآئِقَ غُلْبًا
Transliteration waḥadāiqa ghul'ban
Yoruba àti àwọn ọgbà tó kún fún igi,
Verse 31
وَفَـٰكِهَةً وَأَبًّا
Transliteration wafākihatan wa-abban
Yoruba àti àwọn èso (mìíràn) pẹ̀lú ewé tí ẹranko ń jẹ, (A mú wọn hù jáde).
Verse 32
مَّتَـٰعًا لَّكُمْ وَلِأَنْعَـٰمِكُمْ
Transliteration matāʿan lakum wali-anʿāmikum
Yoruba (Wọ́n jẹ́ n̄ǹkan) ìgbádùn fún ẹ̀yin àti àwọn ẹran-ọ̀sìn yín.
Verse 33
فَإِذَا جَآءَتِ ٱلصَّآخَّةُ
Transliteration fa-idhā jāati l-ṣākhatu
Yoruba Nígbà tí fífọn sínú ìwo nígbà kejì bá ṣẹlẹ̀,
Verse 34
يَوْمَ يَفِرُّ ٱلْمَرْءُ مِنْ أَخِيهِ
Transliteration yawma yafirru l-maru min akhīhi
Yoruba ní ọjọ́ tí ènìyàn yóò sá fún arákùnrin rẹ̀,
Verse 35
وَأُمِّهِۦ وَأَبِيهِ
Transliteration wa-ummihi wa-abīhi
Yoruba àti ìyá rẹ̀ àti bàbá rẹ̀,
Verse 36
وَصَـٰحِبَتِهِۦ وَبَنِيهِ
Transliteration waṣāḥibatihi wabanīhi
Yoruba àti ìyàwó rẹ̀ àti àwọn ọmọ rẹ̀.
Verse 37
لِكُلِّ ٱمْرِئٍ مِّنْهُمْ يَوْمَئِذٍ شَأْنٌ يُغْنِيهِ
Transliteration likulli im'ri-in min'hum yawma-idhin shanun yugh'nīhi
Yoruba Ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn ní ọjọ́ yẹn l’ó ti ní ọ̀ràn tó máa tó o ó rán.
Verse 38
وُجُوهٌ يَوْمَئِذٍ مُّسْفِرَةٌ
Transliteration wujūhun yawma-idhin mus'firatun
Yoruba Àwọn ojú kan lọ́jọ́ yẹn yóò mọ́lẹ̀.
Verse 39
ضَاحِكَةٌ مُّسْتَبْشِرَةٌ
Transliteration ḍāḥikatun mus'tabshiratun
Yoruba Wọn yó máa rẹ́rìn-ín, wọn yó sì máa dunnú.
Verse 40
وَوُجُوهٌ يَوْمَئِذٍ عَلَيْهَا غَبَرَةٌ
Transliteration wawujūhun yawma-idhin ʿalayhā ghabaratun
Yoruba Àwọn ojú kan lọ́jọ́ yẹn ni eruku yó sì bò mọ́lẹ̀.
Verse 41
تَرْهَقُهَا قَتَرَةٌ
Transliteration tarhaquhā qataratun
Yoruba Òkùnkùn yó sì bò wọ́n mọ́lẹ̀.
Verse 42
أُو۟لَـٰٓئِكَ هُمُ ٱلْكَفَرَةُ ٱلْفَجَرَةُ
Transliteration ulāika humu l-kafaratu l-fajaratu
Yoruba Àwọn wọ̀nyẹn gan-an ni aláìgbàgbọ́, ẹlẹ́ṣẹ̀.
Read Surah 'Abasa in another language
- English (word by word)
- Albanian
- Amazigh
- Amharic
- Assamese
- Azerbaijani
- Bambara
- Bangla
- Bosnian
- Bulgarian
- Chechen
- Chinese
- Czech
- Dari
- Dhivehi
- Dutch
- Finnish
- French
- German
- Gujarati
- Hausa
- Hebrew
- Hindi
- Indonesian
- Italian
- Japanese
- Kannada
- Kazakh
- Khmer
- Kinyarwanda
- Korean
- Kurdish
- Luganda
- Malay
- Malayalam
- Maranao
- Marathi
- Nepali
- Norwegian
- Oromo
- Pashto
- Persian
- Polish
- Portuguese
- Romanian
- Russian
- Sindhi
- Sinhala
- Somali
- Spanish
- Swahili
- Swedish
- Tagalog
- Tajik
- Tamil
- Tatar
- Telugu
- Thai
- Turkish
- Ukrainian
- Urdu
- Uyghur
- Uzbek
- Vietnamese
- Yao
All 114 surahs in Yoruba: the Qur’an in Yoruba.
Yoruba translation: Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni, from Quran.com. Transliteration: Quran.com. Recitation: Mishary Alafasy, from EveryAyah.com. MyDugsi is a learning aid, not a replacement for a qualified teacher.