MyDugsiStart learning

Surah Al-Balad in Yoruba: translation and audio

Surah 90 · البلد · The City · 20 verses

Surah Al-Balad verse by verse: the Arabic with a recitation you can repeat, the transliteration, and the Yoruba translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni. For the meaning of every word, see Surah Al-Balad word by word in English.

Verse 1

لَآ أُقْسِمُ بِهَـٰذَا ٱلْبَلَدِ

Transliteration lā uq'simu bihādhā l-baladi

Yoruba Èmi (Allāhu) ń fi ìlú yìíbúra.

Verse 2

وَأَنتَ حِلٌّۢ بِهَـٰذَا ٱلْبَلَدِ

Transliteration wa-anta ḥillun bihādhā l-baladi

Yoruba Ìwọ sì ní ẹ̀tọ́ sí ìlú yìí (láti jagun nínú rẹ̀).1

Verse 3

وَوَالِدٍ وَمَا وَلَدَ

Transliteration wawālidin wamā walada

Yoruba Èmi (Allāhu) ń fi òbí àti ohun tó bí búra.

Verse 4

لَقَدْ خَلَقْنَا ٱلْإِنسَـٰنَ فِى كَبَدٍ

Transliteration laqad khalaqnā l-insāna fī kabadin

Yoruba Dájúdájú A ṣẹ̀dá ènìyàn sínú ìṣòro.

Verse 5

أَيَحْسَبُ أَن لَّن يَقْدِرَ عَلَيْهِ أَحَدٌ

Transliteration ayaḥsabu an lan yaqdira ʿalayhi aḥadun

Yoruba Ṣé ó ń lérò pé ẹnì kan kò ní agbára lórí òun ni?

Verse 6

يَقُولُ أَهْلَكْتُ مَالًا لُّبَدًا

Transliteration yaqūlu ahlaktu mālan lubadan

Yoruba Ó (sì) ń wí pé: “Èmi ti bàná dúkìá ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ (láti fi tako Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -)”

Verse 7

أَيَحْسَبُ أَن لَّمْ يَرَهُۥٓ أَحَدٌ

Transliteration ayaḥsabu an lam yarahu aḥadun

Yoruba Ṣé ó ń lérò pé ẹnì kan kò rí òun ni?

Verse 8

أَلَمْ نَجْعَل لَّهُۥ عَيْنَيْنِ

Transliteration alam najʿal lahu ʿaynayni

Yoruba Ṣé A kò ṣe ojú méjì fún un?

Verse 9

وَلِسَانًا وَشَفَتَيْنِ

Transliteration walisānan washafatayni

Yoruba Àti ahọ́n pẹ̀lú ètè méjì (tí A ṣe fún un)?

Verse 10

وَهَدَيْنَـٰهُ ٱلنَّجْدَيْنِ

Transliteration wahadaynāhu l-najdayni

Yoruba A sì fi ọ̀nà méjì mọ̀ ọ́n.

Verse 11

فَلَا ٱقْتَحَمَ ٱلْعَقَبَةَ

Transliteration falā iq'taḥama l-ʿaqabata

Yoruba Kò sì lọ rin ojú-ọ̀nà orí àpáta tó ṣòroó gùn fún ìgbàlà ẹ̀mí níbi Iná!

Verse 12

وَمَآ أَدْرَىٰكَ مَا ٱلْعَقَبَةُ

Transliteration wamā adrāka mā l-ʿaqabatu

Yoruba Kí sì ni ó mú ọ mọ ohun tó ń jẹ́ ojú-ọ̀nà orí àpáta tó ṣòroó gùn fún ìgbàlà ẹ̀mí?

Verse 13

فَكُّ رَقَبَةٍ

Transliteration fakku raqabatin

Yoruba (Òhun ni) títú ẹrú sílẹ̀ lóko ẹrú.

Verse 14

أَوْ إِطْعَـٰمٌ فِى يَوْمٍ ذِى مَسْغَبَةٍ

Transliteration aw iṭ'ʿāmun fī yawmin dhī masghabatin

Yoruba Tàbí fífún ènìyàn ní oúnjẹ ní ọjọ́ ebi.

Verse 15

يَتِيمًا ذَا مَقْرَبَةٍ

Transliteration yatīman dhā maqrabatin

Yoruba (Ẹ lè fún) ọmọ-òrukàn nínú ẹbí,

Verse 16

أَوْ مِسْكِينًا ذَا مَتْرَبَةٍ

Transliteration aw mis'kīnan dhā matrabatin

Yoruba tàbí mẹ̀kúnnù tí kò ní gá tí kò ní go (olòṣì paraku).

Verse 17

ثُمَّ كَانَ مِنَ ٱلَّذِينَ ءَامَنُوا۟ وَتَوَاصَوْا۟ بِٱلصَّبْرِ وَتَوَاصَوْا۟ بِٱلْمَرْحَمَةِ

Transliteration thumma kāna mina alladhīna āmanū watawāṣaw bil-ṣabri watawāṣaw bil-marḥamati

Yoruba Lẹ́yìn náà, kí ó wà nínú àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n ń gbara wọn níyànjú sùúrù ṣíṣe, tí wọ́n sì tún ń gbara wọn níyànjú àánú ṣíṣe.

Verse 18

أُو۟لَـٰٓئِكَ أَصْحَـٰبُ ٱلْمَيْمَنَةِ

Transliteration ulāika aṣḥābu l-maymanati

Yoruba Àwọn wọ̀nyẹn ni èrò ọwọ́ ọ̀tún.

Verse 19

وَٱلَّذِينَ كَفَرُوا۟ بِـَٔايَـٰتِنَا هُمْ أَصْحَـٰبُ ٱلْمَشْـَٔمَةِ

Transliteration wa-alladhīna kafarū biāyātinā hum aṣḥābu l-mashamati

Yoruba Àwọn tó sì ṣàì gbàgbọ́ nínú àwọn āyah Wa, àwọn ni èrò ọwọ́ òsì.1

Verse 20

عَلَيْهِمْ نَارٌ مُّؤْصَدَةٌۢ

Transliteration ʿalayhim nārun mu'ṣadatun

Yoruba Wọ́n máa ti àwọn ìlẹ̀kùn Iná pa mọ́ wọn lórí pátápátá.

Read Surah Al-Balad in another language

All languages

All 114 surahs in Yoruba: the Qur’an in Yoruba.

Learn it in MyDugsi

Yoruba translation: Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni, from Quran.com. Transliteration: Quran.com. Recitation: Mishary Alafasy, from EveryAyah.com. MyDugsi is a learning aid, not a replacement for a qualified teacher.