Surah Al-Layl in Yoruba: translation and audio
Surah 92 · الليل · The Night · 21 verses
Surah Al-Layl verse by verse: the Arabic with a recitation you can repeat, the transliteration, and the Yoruba translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni. For the meaning of every word, see Surah Al-Layl word by word in English.
Verse 1
وَٱلَّيْلِ إِذَا يَغْشَىٰ
Transliteration wa-al-layli idhā yaghshā
Yoruba Allāhu fi alẹ́ nígbà tí (ilẹ̀) bá ṣú búra.
Verse 2
وَٱلنَّهَارِ إِذَا تَجَلَّىٰ
Transliteration wal-nahāri idhā tajallā
Yoruba Ó tún fi ọ̀sán nígbà tí (ọ̀sán) bá pọ́n búra.
Verse 3
وَمَا خَلَقَ ٱلذَّكَرَ وَٱلْأُنثَىٰٓ
Transliteration wamā khalaqa l-dhakara wal-unthā
Yoruba Ó tún fi Ẹni tí Ó dá akọ àti abo búra.1
Verse 4
إِنَّ سَعْيَكُمْ لَشَتَّىٰ
Transliteration inna saʿyakum lashattā
Yoruba Dájúdájú ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni iṣẹ́ yín.
Verse 5
فَأَمَّا مَنْ أَعْطَىٰ وَٱتَّقَىٰ
Transliteration fa-ammā man aʿṭā wa-ittaqā
Yoruba Ní ti ẹni tí ó bá tọrẹ, tí ó sì bẹ̀rù (Allāhu),
Verse 6
وَصَدَّقَ بِٱلْحُسْنَىٰ
Transliteration waṣaddaqa bil-ḥus'nā
Yoruba (tí) ó tún pe ẹ̀san rere (Ọgbà Ìdẹ̀ra) ní òdodo,
Verse 7
فَسَنُيَسِّرُهُۥ لِلْيُسْرَىٰ
Transliteration fasanuyassiruhu lil'yus'rā
Yoruba A sì máa ṣe iṣẹ́ rere ní ìrọ̀rùn fún un.
Verse 8
وَأَمَّا مَنۢ بَخِلَ وَٱسْتَغْنَىٰ
Transliteration wa-ammā man bakhila wa-is'taghnā
Yoruba Ní ti ẹni tí ó bá yahun, tí ó sì rí ara rẹ̀ lẹ́ni tó rọrọ̀ tayọ ẹ̀san ọ̀run,
Verse 9
وَكَذَّبَ بِٱلْحُسْنَىٰ
Transliteration wakadhaba bil-ḥus'nā
Yoruba (tí) ó tún pe ẹ̀san rere (Ọgbà Ìdẹ̀ra) ní irọ́,
Verse 10
فَسَنُيَسِّرُهُۥ لِلْعُسْرَىٰ
Transliteration fasanuyassiruhu lil'ʿus'rā
Yoruba A sì máa ṣe iṣẹ́ aburú ní ìrọ̀rùn fún un.
Verse 11
وَمَا يُغْنِى عَنْهُ مَالُهُۥٓ إِذَا تَرَدَّىٰٓ
Transliteration wamā yugh'nī ʿanhu māluhu idhā taraddā
Yoruba Dúkìá rẹ̀ kò sì níí rọ̀ ọ́ lọ́rọ̀ nígbà tí ó bá parun, tí ó já bọ́ (sínú Iná).
Verse 12
إِنَّ عَلَيْنَا لَلْهُدَىٰ
Transliteration inna ʿalaynā lalhudā
Yoruba Dájúdájú tiWa ni (láti ṣàlàyé) ìmọ̀nà.
Verse 13
وَإِنَّ لَنَا لَلْـَٔاخِرَةَ وَٱلْأُولَىٰ
Transliteration wa-inna lanā lalākhirata wal-ūlā
Yoruba Àti pé dájúdájú tiWa ni ọ̀run àti ayé.
Verse 14
فَأَنذَرْتُكُمْ نَارًا تَلَظَّىٰ
Transliteration fa-andhartukum nāran talaẓẓā
Yoruba Nítorí náà, Mo ti fi Iná tó ń jò fòfò kìlọ̀ fún yín.
Verse 15
لَا يَصْلَىٰهَآ إِلَّا ٱلْأَشْقَى
Transliteration lā yaṣlāhā illā l-ashqā
Yoruba Kò sí ẹni tí ó máa wọ inú rẹ̀ àfi olórí burúkú,
Verse 16
ٱلَّذِى كَذَّبَ وَتَوَلَّىٰ
Transliteration alladhī kadhaba watawallā
Yoruba ẹni tí ó pe òdodo ní irọ́, tí ó sì kẹ̀yìn sí i.
Verse 17
وَسَيُجَنَّبُهَا ٱلْأَتْقَى
Transliteration wasayujannabuhā l-atqā
Yoruba Wọ́n sì máa gbé (Iná) jìnnà sí olùbẹ̀rù (Allāhu),
Verse 18
ٱلَّذِى يُؤْتِى مَالَهُۥ يَتَزَكَّىٰ
Transliteration alladhī yu'tī mālahu yatazakkā
Yoruba ẹni tó ń fi dúkìá rẹ̀ tọrẹ, tí ó ń ṣàfọ̀mọ́ (rẹ̀).
Verse 19
وَمَا لِأَحَدٍ عِندَهُۥ مِن نِّعْمَةٍ تُجْزَىٰٓ
Transliteration wamā li-aḥadin ʿindahu min niʿ'matin tuj'zā
Yoruba Kò sì sí oore ìdẹ̀ra kan tí (ó ní lọ́kàn) láti gbà ní ẹ̀san ní ọ̀dọ̀ ẹnikẹ́ni,
Verse 20
إِلَّا ٱبْتِغَآءَ وَجْهِ رَبِّهِ ٱلْأَعْلَىٰ
Transliteration illā ib'tighāa wajhi rabbihi l-aʿlā
Yoruba bí kò ṣe pé láti fi wá ojú rere Olúwa rẹ̀, Ẹni Gíga jùlọ.
Verse 21
وَلَسَوْفَ يَرْضَىٰ
Transliteration walasawfa yarḍā
Yoruba Láìpẹ́ ó sì máa yọ́nú (sí ẹ̀san rere rẹ̀).
Read Surah Al-Layl in another language
- English (word by word)
- Albanian
- Amazigh
- Amharic
- Assamese
- Azerbaijani
- Bambara
- Bangla
- Bosnian
- Bulgarian
- Chechen
- Chinese
- Czech
- Dari
- Dhivehi
- Dutch
- Finnish
- French
- German
- Gujarati
- Hausa
- Hebrew
- Hindi
- Indonesian
- Italian
- Japanese
- Kannada
- Kazakh
- Khmer
- Kinyarwanda
- Korean
- Kurdish
- Luganda
- Malay
- Malayalam
- Maranao
- Marathi
- Nepali
- Norwegian
- Oromo
- Pashto
- Persian
- Polish
- Portuguese
- Romanian
- Russian
- Sindhi
- Sinhala
- Somali
- Spanish
- Swahili
- Swedish
- Tagalog
- Tajik
- Tamil
- Tatar
- Telugu
- Thai
- Turkish
- Ukrainian
- Urdu
- Uyghur
- Uzbek
- Vietnamese
- Yao
All 114 surahs in Yoruba: the Qur’an in Yoruba.
Yoruba translation: Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni, from Quran.com. Transliteration: Quran.com. Recitation: Mishary Alafasy, from EveryAyah.com. MyDugsi is a learning aid, not a replacement for a qualified teacher.