Surah Al-Mursalat in Yoruba: translation and audio
Surah 77 · المرسلات · The Emissaries · 50 verses
Surah Al-Mursalat verse by verse: the Arabic with a recitation you can repeat, the transliteration, and the Yoruba translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni. For the meaning of every word, see Surah Al-Mursalat word by word in English.
Verse 1
وَٱلْمُرْسَلَـٰتِ عُرْفًا
Transliteration wal-mur'salāti ʿur'fan
Yoruba Allāhu fi àwọn atẹ́gùn tó ń sáré ní tẹ̀léǹtẹ̀lé búra.
Verse 2
فَٱلْعَـٰصِفَـٰتِ عَصْفًا
Transliteration fal-ʿāṣifāti ʿaṣfan
Yoruba Ó fi àwọn ìjì atẹ́gùn tó ń jà búra.
Verse 3
وَٱلنَّـٰشِرَٰتِ نَشْرًا
Transliteration wal-nāshirāti nashran
Yoruba Ó fi àwọn atẹ́gùn tó ń tú èṣújò ká búra.
Verse 4
فَٱلْفَـٰرِقَـٰتِ فَرْقًا
Transliteration fal-fāriqāti farqan
Yoruba Ó fi àwọn tó ń ṣèpínyà láààrin òdodo àti irọ́ búra.
Verse 5
فَٱلْمُلْقِيَـٰتِ ذِكْرًا
Transliteration fal-mul'qiyāti dhik'ran
Yoruba Ó fi àwọn mọlāika tó ń mú ìrántí wá (bá àwọn Òjíṣẹ́) búra.
Verse 6
عُذْرًا أَوْ نُذْرًا
Transliteration ʿudh'ran aw nudh'ran
Yoruba (Ìrántí náà jẹ́) àwíjàre tàbí ìkìlọ̀.
Verse 7
إِنَّمَا تُوعَدُونَ لَوَٰقِعٌ
Transliteration innamā tūʿadūna lawāqiʿun
Yoruba Dájúdájú ohun tí A ṣe ní àdéhùn fún yín kúkú máa ṣẹlẹ̀.
Verse 8
فَإِذَا ٱلنُّجُومُ طُمِسَتْ
Transliteration fa-idhā l-nujūmu ṭumisat
Yoruba Nítorí náà, nígbà tí wọ́n bá pa (ìmọ́lẹ̀) ìràwọ̀ rẹ́,
Verse 9
وَإِذَا ٱلسَّمَآءُ فُرِجَتْ
Transliteration wa-idhā l-samāu furijat
Yoruba àti nígbà tí wọ́n bá ṣí sánmọ̀ sílẹ̀ gbagada,
Verse 10
وَإِذَا ٱلْجِبَالُ نُسِفَتْ
Transliteration wa-idhā l-jibālu nusifat
Yoruba àti nígbà tí wọ́n bá ku àwọn àpáta dànù,
Verse 11
وَإِذَا ٱلرُّسُلُ أُقِّتَتْ
Transliteration wa-idhā l-rusulu uqqitat
Yoruba àti nígbà tí wọ́n bá fún àwọn Òjíṣẹ́ ní àsìkò láti kójọ (pẹ̀lú ìjọ wọn),
Verse 12
لِأَىِّ يَوْمٍ أُجِّلَتْ
Transliteration li-ayyi yawmin ujjilat
Yoruba ọjọ́ wo ni wọ́n so (àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ wọ̀nyí) rọ̀ fún ná?
Verse 13
لِيَوْمِ ٱلْفَصْلِ
Transliteration liyawmi l-faṣli
Yoruba Fún ọjọ́ ìpínyà (láààrin àwọn ẹ̀dá) ni.
Verse 14
وَمَآ أَدْرَىٰكَ مَا يَوْمُ ٱلْفَصْلِ
Transliteration wamā adrāka mā yawmu l-faṣli
Yoruba Kí sì ni ó mú ọ mọ ohun tó ń jẹ́ Ọjọ́ ìpínyà?
Verse 15
وَيْلٌ يَوْمَئِذٍ لِّلْمُكَذِّبِينَ
Transliteration waylun yawma-idhin lil'mukadhibīna
Yoruba Ègbé ni ní ọjọ́ yẹn fún àwọn olùpe-òdodo-nírọ́.
Verse 16
أَلَمْ نُهْلِكِ ٱلْأَوَّلِينَ
Transliteration alam nuh'liki l-awalīna
Yoruba Ǹjẹ́ Àwa kò ti pa àwọn ẹni àkọ́kọ́ rẹ́ bí?
Verse 17
ثُمَّ نُتْبِعُهُمُ ٱلْـَٔاخِرِينَ
Transliteration thumma nut'biʿuhumu l-ākhirīna
Yoruba Lẹ́yìn náà, A sì máa fi àwọn ẹni Ìkẹ́yìn tẹ̀lé wọn (nínú ìparun).
Verse 18
كَذَٰلِكَ نَفْعَلُ بِٱلْمُجْرِمِينَ
Transliteration kadhālika nafʿalu bil-muj'rimīna
Yoruba Báyẹn ni A ó ti ṣe pẹ̀lú àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀.
Verse 19
وَيْلٌ يَوْمَئِذٍ لِّلْمُكَذِّبِينَ
Transliteration waylun yawma-idhin lil'mukadhibīna
Yoruba Ègbé ni ní ọjọ́ yẹn fún àwọn olùpe-òdodo-nírọ́.
Verse 20
أَلَمْ نَخْلُقكُّم مِّن مَّآءٍ مَّهِينٍ
Transliteration alam nakhluqkkum min māin mahīnin
Yoruba Ṣé A kò ṣẹ̀dá yin láti inú omi lílẹ yẹpẹrẹ bí?
Verse 21
فَجَعَلْنَـٰهُ فِى قَرَارٍ مَّكِينٍ
Transliteration fajaʿalnāhu fī qarārin makīnin
Yoruba Lẹ́yìn náà, A fi sínú àyè ààbò (ìyẹn, ilé-ọmọ)
Verse 22
إِلَىٰ قَدَرٍ مَّعْلُومٍ
Transliteration ilā qadarin maʿlūmin
Yoruba títí di gbèdéke àkókò kan tí A ti mọ̀ (ìyen, ọjọ́ ìbímọ).
Verse 23
فَقَدَرْنَا فَنِعْمَ ٱلْقَـٰدِرُونَ
Transliteration faqadarnā faniʿ'ma l-qādirūna
Yoruba A sì ní ìkápá àti àyànmọ́ (lórí rẹ̀. Àwa sì ni) Olùkápá àti Olùpèbùbù ẹ̀dá tó dára.
Verse 24
وَيْلٌ يَوْمَئِذٍ لِّلْمُكَذِّبِينَ
Transliteration waylun yawma-idhin lil'mukadhibīna
Yoruba Ègbé ni ní ọjọ́ yẹn fún àwọn olùpe-òdodo-nírọ́.
Verse 25
أَلَمْ نَجْعَلِ ٱلْأَرْضَ كِفَاتًا
Transliteration alam najʿali l-arḍa kifātan
Yoruba Ǹjẹ́ Àwa kò ṣe ilẹ̀ ní ohun tó ń kó ẹ̀dá jọ mọ́ra wọn;
Verse 26
أَحْيَآءً وَأَمْوَٰتًا
Transliteration aḥyāan wa-amwātan
Yoruba (ìyẹn) àwọn alààyè àti àwọn òkú?
Verse 27
وَجَعَلْنَا فِيهَا رَوَٰسِىَ شَـٰمِخَـٰتٍ وَأَسْقَيْنَـٰكُم مَّآءً فُرَاتًا
Transliteration wajaʿalnā fīhā rawāsiya shāmikhātin wa-asqaynākum māan furātan
Yoruba A sì fi àwọn àpáta gbagidi gíga-gíga sínú rẹ̀. A sì fún yín ní omi dídùn mu.
Verse 28
وَيْلٌ يَوْمَئِذٍ لِّلْمُكَذِّبِينَ
Transliteration waylun yawma-idhin lil'mukadhibīna
Yoruba Ègbé ni ní ọjọ́ yẹn fún àwọn olùpe-òdodo-nírọ́.
Verse 29
ٱنطَلِقُوٓا۟ إِلَىٰ مَا كُنتُم بِهِۦ تُكَذِّبُونَ
Transliteration inṭaliqū ilā mā kuntum bihi tukadhibūna
Yoruba Ẹ máa lọ sí ibi tí ẹ̀ ń pè ní irọ́.
Verse 30
ٱنطَلِقُوٓا۟ إِلَىٰ ظِلٍّ ذِى ثَلَـٰثِ شُعَبٍ
Transliteration inṭaliqū ilā ẓillin dhī thalāthi shuʿabin
Yoruba Ẹ máa lọ sí ibi èéfín ẹlẹ́ka mẹ́ta.
Verse 31
لَّا ظَلِيلٍ وَلَا يُغْنِى مِنَ ٱللَّهَبِ
Transliteration lā ẓalīlin walā yugh'nī mina l-lahabi
Yoruba Kì í ṣe ibòji tútù. Kò sì níí rọ̀ wọ́n lọ́rọ̀ nínú ìjòfòfò Iná.
Verse 32
إِنَّهَا تَرْمِى بِشَرَرٍ كَٱلْقَصْرِ
Transliteration innahā tarmī bishararin kal-qaṣri
Yoruba Dájúdájú (Iná náà) yóò máa ju ẹ̀tapàrà (rẹ̀ sókè tó máa dà) bí pẹ̀tẹ́ẹ̀sì.
Verse 33
كَأَنَّهُۥ جِمَـٰلَتٌ صُفْرٌ
Transliteration ka-annahu jimālatun ṣuf'run
Yoruba (Ó máa dà) bí àwọn ràkúnmí aláwọ̀ omi ọsàn.
Verse 34
وَيْلٌ يَوْمَئِذٍ لِّلْمُكَذِّبِينَ
Transliteration waylun yawma-idhin lil'mukadhibīna
Yoruba Ègbé ni ní ọjọ́ yẹn fún àwọn olùpe-òdodo-nírọ́
Verse 35
هَـٰذَا يَوْمُ لَا يَنطِقُونَ
Transliteration hādhā yawmu lā yanṭiqūna
Yoruba Èyí ni ọjọ́ tí wọn kò níí sọ̀rọ̀.
Verse 36
وَلَا يُؤْذَنُ لَهُمْ فَيَعْتَذِرُونَ
Transliteration walā yu'dhanu lahum fayaʿtadhirūna
Yoruba A kò sì níí yọ̀ǹda (ọ̀rọ̀ sísọ) fún wọn, áḿbọ̀sìbọ́sí pé wọ́n yóò mú àwáwí wá.
Verse 37
وَيْلٌ يَوْمَئِذٍ لِّلْمُكَذِّبِينَ
Transliteration waylun yawma-idhin lil'mukadhibīna
Yoruba Ègbé ni ní ọjọ́ yẹn fún àwọn olùpe-òdodo-nírọ́.
Verse 38
هَـٰذَا يَوْمُ ٱلْفَصْلِ ۖ جَمَعْنَـٰكُمْ وَٱلْأَوَّلِينَ
Transliteration hādhā yawmu l-faṣli jamaʿnākum wal-awalīna
Yoruba Èyí ni ọjọ́ ìpínyà. Àwa yó sì kó ẹ̀yin àti àwọn ẹni àkọ́kọ́ jọ.
Verse 39
فَإِن كَانَ لَكُمْ كَيْدٌ فَكِيدُونِ
Transliteration fa-in kāna lakum kaydun fakīdūni
Yoruba Tí ẹ bá ní ète kan lọ́wọ́, ẹ déte sí Mi wò.
Verse 40
وَيْلٌ يَوْمَئِذٍ لِّلْمُكَذِّبِينَ
Transliteration waylun yawma-idhin lil'mukadhibīna
Yoruba Ègbé ni ní ọjọ́ yẹn fún àwọn olùpe-òdodo-nírọ́.
Verse 41
إِنَّ ٱلْمُتَّقِينَ فِى ظِلَـٰلٍ وَعُيُونٍ
Transliteration inna l-mutaqīna fī ẓilālin waʿuyūnin
Yoruba Dájúdájú àwọn olùbẹ̀rù Allāhu yóò wà níbi ibòji àti àwọn omi ìṣẹ́lẹ̀rú,
Verse 42
وَفَوَٰكِهَ مِمَّا يَشْتَهُونَ
Transliteration wafawākiha mimmā yashtahūna
Yoruba àti àwọn èso èyí tí wọ́n bá ń fẹ́.
Verse 43
كُلُوا۟ وَٱشْرَبُوا۟ هَنِيٓـًٔۢا بِمَا كُنتُمْ تَعْمَلُونَ
Transliteration kulū wa-ish'rabū hanīan bimā kuntum taʿmalūna
Yoruba Ẹ jẹ, kí ẹ sì mu pẹ̀lú ìgbádùn nítorí ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.
Verse 44
إِنَّا كَذَٰلِكَ نَجْزِى ٱلْمُحْسِنِينَ
Transliteration innā kadhālika najzī l-muḥ'sinīna
Yoruba Dájúdájú báyẹn ni Àwa ṣe ń san àwọn olùṣe-rere ní ẹ̀san (rere).
Verse 45
وَيْلٌ يَوْمَئِذٍ لِّلْمُكَذِّبِينَ
Transliteration waylun yawma-idhin lil'mukadhibīna
Yoruba Ègbé ni ní ọjọ́ yẹn fún àwọn olùpe-òdodo-nírọ́.
Verse 46
كُلُوا۟ وَتَمَتَّعُوا۟ قَلِيلًا إِنَّكُم مُّجْرِمُونَ
Transliteration kulū watamattaʿū qalīlan innakum muj'rimūna
Yoruba Ẹ jẹ, kí ẹ sì gbádùn fún ìgbà díẹ̀. Dájúdájú ẹlẹ́ṣẹ̀ ni yín.
Verse 47
وَيْلٌ يَوْمَئِذٍ لِّلْمُكَذِّبِينَ
Transliteration waylun yawma-idhin lil'mukadhibīna
Yoruba Ègbé ni ní ọjọ́ yẹn fún àwọn olùpe-òdodo-nírọ́.
Verse 48
وَإِذَا قِيلَ لَهُمُ ٱرْكَعُوا۟ لَا يَرْكَعُونَ
Transliteration wa-idhā qīla lahumu ir'kaʿū lā yarkaʿūna
Yoruba Nígbà tí wọ́n bá sọ fún wọn pé kí wọ́n kírun, wọn kò níí kírun.
Verse 49
وَيْلٌ يَوْمَئِذٍ لِّلْمُكَذِّبِينَ
Transliteration waylun yawma-idhin lil'mukadhibīna
Yoruba Ègbé ni ní ọjọ́ yẹn fún àwọn olùpe-òdodo-nírọ́.
Verse 50
فَبِأَىِّ حَدِيثٍۭ بَعْدَهُۥ يُؤْمِنُونَ
Transliteration fabi-ayyi ḥadīthin baʿdahu yu'minūna
Yoruba Nígbà náà, ọ̀rọ̀ wo ni wọn yóò gbàgbọ́ lẹ́yìn rẹ̀?1
Read Surah Al-Mursalat in another language
- English (word by word)
- Albanian
- Amazigh
- Amharic
- Assamese
- Azerbaijani
- Bambara
- Bangla
- Bosnian
- Bulgarian
- Chechen
- Chinese
- Czech
- Dari
- Dhivehi
- Dutch
- Finnish
- French
- German
- Gujarati
- Hausa
- Hebrew
- Hindi
- Indonesian
- Italian
- Japanese
- Kannada
- Kazakh
- Khmer
- Kinyarwanda
- Korean
- Kurdish
- Luganda
- Malay
- Malayalam
- Maranao
- Marathi
- Nepali
- Norwegian
- Oromo
- Pashto
- Persian
- Polish
- Portuguese
- Romanian
- Russian
- Sindhi
- Sinhala
- Somali
- Spanish
- Swahili
- Swedish
- Tagalog
- Tajik
- Tamil
- Tatar
- Telugu
- Thai
- Turkish
- Ukrainian
- Urdu
- Uyghur
- Uzbek
- Vietnamese
- Yao
All 114 surahs in Yoruba: the Qur’an in Yoruba.
Yoruba translation: Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni, from Quran.com. Transliteration: Quran.com. Recitation: Mishary Alafasy, from EveryAyah.com. MyDugsi is a learning aid, not a replacement for a qualified teacher.