MyDugsiStart learning

Surah Al-'Alaq in Yoruba: translation and audio

Surah 96 · العلق · The Clot · 19 verses

Surah Al-'Alaq verse by verse: the Arabic with a recitation you can repeat, the transliteration, and the Yoruba translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni. For the meaning of every word, see Surah Al-'Alaq word by word in English.

Verse 1

ٱقْرَأْ بِٱسْمِ رَبِّكَ ٱلَّذِى خَلَقَ

Transliteration iq'ra bi-is'mi rabbika alladhī khalaqa

Yoruba Ké (al-Ƙur’ān) pẹ̀lú orúkọ Olúwa rẹ, Ẹni tí Ó dá ẹ̀dá.

Verse 2

خَلَقَ ٱلْإِنسَـٰنَ مِنْ عَلَقٍ

Transliteration khalaqa l-insāna min ʿalaqin

Yoruba Ó ṣẹ̀dá ènìyàn láti ara ẹ̀jẹ̀ dídì.

Verse 3

ٱقْرَأْ وَرَبُّكَ ٱلْأَكْرَمُ

Transliteration iq'ra warabbuka l-akramu

Yoruba Ké e. Olúwa rẹ ni Alápọ̀n-ọ́nlé jùlọ.

Verse 4

ٱلَّذِى عَلَّمَ بِٱلْقَلَمِ

Transliteration alladhī ʿallama bil-qalami

Yoruba Ẹni tí Ó fi ìmọ̀ nípa gègé ìkọ̀wé mọ ènìyàn.

Verse 5

عَلَّمَ ٱلْإِنسَـٰنَ مَا لَمْ يَعْلَمْ

Transliteration ʿallama l-insāna mā lam yaʿlam

Yoruba Ó fi ìmọ̀ tí ènìyàn kò mọ̀ mọ̀ ọ́n.

Verse 6

كَلَّآ إِنَّ ٱلْإِنسَـٰنَ لَيَطْغَىٰٓ

Transliteration kallā inna l-insāna layaṭghā

Yoruba Ní ti òdodo, dájúdájú ènìyàn kúkú ń tayọ ẹnu-ààlà

Verse 7

أَن رَّءَاهُ ٱسْتَغْنَىٰٓ

Transliteration an raāhu is'taghnā

Yoruba nítorí pé ó rí ara rẹ̀ ní ọlọ́rọ̀.

Verse 8

إِنَّ إِلَىٰ رَبِّكَ ٱلرُّجْعَىٰٓ

Transliteration inna ilā rabbika l-ruj'ʿā

Yoruba Dájúdájú ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ ni àbọ̀ ẹ̀dá.

Verse 9

أَرَءَيْتَ ٱلَّذِى يَنْهَىٰ

Transliteration ara-ayta alladhī yanhā

Yoruba Sọ fún mi nípa ẹni tó ń kọ̀

Verse 10

عَبْدًا إِذَا صَلَّىٰٓ

Transliteration ʿabdan idhā ṣallā

Yoruba fún ẹrúsìn kan nígbà tí (ẹrúsìn náà) kírun!

Verse 11

أَرَءَيْتَ إِن كَانَ عَلَى ٱلْهُدَىٰٓ

Transliteration ara-ayta in kāna ʿalā l-hudā

Yoruba Sọ fún mi (nípa ẹ̀san rẹ̀) tí ó bá jẹ́ pé ó wà lórí ìmọ̀nà (’Islām)

Verse 12

أَوْ أَمَرَ بِٱلتَّقْوَىٰٓ

Transliteration aw amara bil-taqwā

Yoruba tàbí pé ó pàṣẹ ìbẹ̀rù (Allāhu)!

Verse 13

أَرَءَيْتَ إِن كَذَّبَ وَتَوَلَّىٰٓ

Transliteration ara-ayta in kadhaba watawallā

Yoruba Sọ fún mi (nípa ìyà rẹ̀) tí ó bá jẹ́ pé ó pe òdodo ní irọ́, tí ó sì kẹ̀yìn sí i?

Verse 14

أَلَمْ يَعْلَم بِأَنَّ ٱللَّهَ يَرَىٰ

Transliteration alam yaʿlam bi-anna l-laha yarā

Yoruba Ṣé kò mọ̀ pé dájúdájú Allāhu ń rí (òun ni?)

Verse 15

كَلَّا لَئِن لَّمْ يَنتَهِ لَنَسْفَعًۢا بِٱلنَّاصِيَةِ

Transliteration kallā la-in lam yantahi lanasfaʿan bil-nāṣiyati

Yoruba Rárá (ọ̀rọ̀ kò rí bí ọ̀tá Allāhu ṣe rò ó sí. Dájúdájú tí kò bá jáwọ́ (níbi dídí Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - lọ́wọ́), dájúdájú A máa fi àásó orí2 rẹ̀ wọ́ ọ (sínú Iná);

Verse 16

نَاصِيَةٍ كَـٰذِبَةٍ خَاطِئَةٍ

Transliteration nāṣiyatin kādhibatin khāṭi-atin

Yoruba àásó orí òpùrọ́, ẹlẹ́ṣẹ̀.

Verse 17

فَلْيَدْعُ نَادِيَهُۥ

Transliteration falyadʿu nādiyahu

Yoruba Nítorí náà, kí ó pe àwọn olùbájókòó rẹ̀.

Verse 18

سَنَدْعُ ٱلزَّبَانِيَةَ

Transliteration sanadʿu l-zabāniyata

Yoruba Àwa máa pe àwọn mọlāika ẹ̀ṣọ́ Iná.

Verse 19

كَلَّا لَا تُطِعْهُ وَٱسْجُدْ وَٱقْتَرِب ۩

Transliteration kallā lā tuṭiʿ'hu wa-us'jud wa-iq'tarib

Yoruba Rárá (ọ̀rọ̀ kò rí bí ó ṣe ń sọ nípa Wa). Má ṣe tẹ̀lé tirẹ̀. Forí kanlẹ̀ (kí o kírun), kí o sì súnmọ́ (Allāhu).

Read Surah Al-'Alaq in another language

All languages

All 114 surahs in Yoruba: the Qur’an in Yoruba.

Learn it in MyDugsi

Yoruba translation: Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni, from Quran.com. Transliteration: Quran.com. Recitation: Mishary Alafasy, from EveryAyah.com. MyDugsi is a learning aid, not a replacement for a qualified teacher.