MyDugsiStart learning

Surah An-Nazi'at in Yoruba: translation and audio

Surah 79 · النازعات · Those who drag forth · 46 verses

Surah An-Nazi'at verse by verse: the Arabic with a recitation you can repeat, the transliteration, and the Yoruba translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni. For the meaning of every word, see Surah An-Nazi'at word by word in English.

Verse 1

وَٱلنَّـٰزِعَـٰتِ غَرْقًا

Transliteration wal-nāziʿāti gharqan

Yoruba Allāhu fi àwọn mọlāika tó ń fi ọ̀nà èle gba ẹ̀mí àwọn aláìgbàgbọ́ búra.

Verse 2

وَٱلنَّـٰشِطَـٰتِ نَشْطًا

Transliteration wal-nāshiṭāti nashṭan

Yoruba Ó tún fi àwọn mọlāika tó ń fi ọ̀nà ẹ̀rọ̀ gba ẹ̀mí àwọn onígbàgbọ́ òdodo búra.

Verse 3

وَٱلسَّـٰبِحَـٰتِ سَبْحًا

Transliteration wal-sābiḥāti sabḥan

Yoruba Ó tún fi àwọn mọlāika tó ń yára gágá níbi àṣẹ Rẹ̀ búra.

Verse 4

فَٱلسَّـٰبِقَـٰتِ سَبْقًا

Transliteration fal-sābiqāti sabqan

Yoruba Ó tún fi àwọn mọlāika tó máa ṣíwájú ẹ̀mí àwọn onígbàgbọ́ òdodo wọnú Ọgbà Ìdẹ̀ra tààrà búra.

Verse 5

فَٱلْمُدَبِّرَٰتِ أَمْرًا

Transliteration fal-mudabirāti amran

Yoruba Ó tún fi àwọn mọlāika tó ń ṣètò nínú sánmọ̀ àti ilé ayé pẹ̀lú àṣẹ Allāhu búra.

Verse 6

يَوْمَ تَرْجُفُ ٱلرَّاجِفَةُ

Transliteration yawma tarjufu l-rājifatu

Yoruba Ní ọjọ́ tí ìmìtìtì máa mi gbogbo ayé tìtì.1

Verse 7

تَتْبَعُهَا ٱلرَّادِفَةُ

Transliteration tatbaʿuhā l-rādifatu

Yoruba Ohun tí ó máa tẹ̀lé e máa ṣẹlẹ̀ tẹ̀lé e.1

Verse 8

قُلُوبٌ يَوْمَئِذٍ وَاجِفَةٌ

Transliteration qulūbun yawma-idhin wājifatun

Yoruba Àwọn ọkàn yóò máa gbọ̀n pẹ̀pẹ̀ ní ọjọ́ yẹn.

Verse 9

أَبْصَـٰرُهَا خَـٰشِعَةٌ

Transliteration abṣāruhā khāshiʿatun

Yoruba Ojú wọn yó sì wálẹ̀ ní ti ìyẹpẹrẹ.

Verse 10

يَقُولُونَ أَءِنَّا لَمَرْدُودُونَ فِى ٱلْحَافِرَةِ

Transliteration yaqūlūna a-innā lamardūdūna fī l-ḥāfirati

Yoruba Wọn yóò wí pé: “Ṣé Wọ́n tún máa dá wa padà sí ìbẹ̀rẹ̀ ìṣẹ̀mí (bíi tayé ni)?

Verse 11

أَءِذَا كُنَّا عِظَـٰمًا نَّخِرَةً

Transliteration a-idhā kunnā ʿiẓāman nakhiratan

Yoruba Ṣé nígbà tí a ti di eegun tó kẹfun tán?”

Verse 12

قَالُوا۟ تِلْكَ إِذًا كَرَّةٌ خَاسِرَةٌ

Transliteration qālū til'ka idhan karratun khāsiratun

Yoruba Wọ́n wí pé: “Ìdápadà òfò nìyẹn nígbà náà (fún ẹni tó pè é ní irọ́.)”

Verse 13

فَإِنَّمَا هِىَ زَجْرَةٌ وَٰحِدَةٌ

Transliteration fa-innamā hiya zajratun wāḥidatun

Yoruba Nítorí náà, igbe ẹyọ kan sì ni.

Verse 14

فَإِذَا هُم بِٱلسَّاهِرَةِ

Transliteration fa-idhā hum bil-sāhirati

Yoruba Nígbà náà ni wọn yóò bára wọn lórí ilẹ̀ gban̄sasa.

Verse 15

هَلْ أَتَىٰكَ حَدِيثُ مُوسَىٰٓ

Transliteration hal atāka ḥadīthu mūsā

Yoruba Ǹjẹ́ ọ̀rọ̀ (Ànábì) Mūsā ti dé ọ̀dọ̀ rẹ?

Verse 16

إِذْ نَادَىٰهُ رَبُّهُۥ بِٱلْوَادِ ٱلْمُقَدَّسِ طُوًى

Transliteration idh nādāhu rabbuhu bil-wādi l-muqadasi ṭuwan

Yoruba (Rántí) nígbà tí Olúwa rẹ̀ pè é ní àfonúfojì mímọ́, Tuwā.

Verse 17

ٱذْهَبْ إِلَىٰ فِرْعَوْنَ إِنَّهُۥ طَغَىٰ

Transliteration idh'hab ilā fir'ʿawna innahu ṭaghā

Yoruba Lọ bá Fir‘aon, dájúdájú ó ti tayọ ẹnu-ààlà.

Verse 18

فَقُلْ هَل لَّكَ إِلَىٰٓ أَن تَزَكَّىٰ

Transliteration faqul hal laka ilā an tazakkā

Yoruba Kí o sì sọ pé: “Ǹjẹ o máa ṣàfọ̀mọ́ ara rẹ (kúrò nínú àìgbàgbọ́) bí?

Verse 19

وَأَهْدِيَكَ إِلَىٰ رَبِّكَ فَتَخْشَىٰ

Transliteration wa-ahdiyaka ilā rabbika fatakhshā

Yoruba Kí èmi sì fi ọ̀nà mọ̀ ọ́ dé ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ, kí o sì páyà (Rẹ̀).”

Verse 20

فَأَرَىٰهُ ٱلْـَٔايَةَ ٱلْكُبْرَىٰ

Transliteration fa-arāhu l-āyata l-kub'rā

Yoruba Ó sì fi àmì tó tóbi hàn án.

Verse 21

فَكَذَّبَ وَعَصَىٰ

Transliteration fakadhaba waʿaṣā

Yoruba (Àmọ́) ó pè é ní òpùrọ́. Ó sì yapa (rẹ̀).

Verse 22

ثُمَّ أَدْبَرَ يَسْعَىٰ

Transliteration thumma adbara yasʿā

Yoruba Lẹ́yìn náà, ó kẹ̀yìn sí i. Ó sì ń ṣiṣẹ́ (takò ó).

Verse 23

فَحَشَرَ فَنَادَىٰ

Transliteration faḥashara fanādā

Yoruba Ó kó (àwọn ènìyàn) jọ, ó sì ké gbàjarì.

Verse 24

فَقَالَ أَنَا۠ رَبُّكُمُ ٱلْأَعْلَىٰ

Transliteration faqāla anā rabbukumu l-aʿlā

Yoruba Ó sì wí pé: “Èmi ni olúwa yín, ẹni gíga jùlọ.”

Verse 25

فَأَخَذَهُ ٱللَّهُ نَكَالَ ٱلْـَٔاخِرَةِ وَٱلْأُولَىٰٓ

Transliteration fa-akhadhahu l-lahu nakāla l-ākhirati wal-ūlā

Yoruba Nítorí náà, Allāhu gbá a mú pẹ̀lú ìyà ìkẹ́yìn àti àkọ́kọ́ (nípa ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀ ìkẹ́yìn yìí àti àkọ́kọ́).1

Verse 26

إِنَّ فِى ذَٰلِكَ لَعِبْرَةً لِّمَن يَخْشَىٰٓ

Transliteration inna fī dhālika laʿib'ratan liman yakhshā

Yoruba Dájúdájú àríwòye wà nínú ìyẹn fún ẹni tó ń páyà (Allāhu).

Verse 27

ءَأَنتُمْ أَشَدُّ خَلْقًا أَمِ ٱلسَّمَآءُ ۚ بَنَىٰهَا

Transliteration a-antum ashaddu khalqan ami l-samāu banāhā

Yoruba Ṣé ẹ̀yin lẹ lágbára jùlọ ní ìṣẹ̀dá ni tàbí sánmọ̀ tí Allāhu mọ?

Verse 28

رَفَعَ سَمْكَهَا فَسَوَّىٰهَا

Transliteration rafaʿa samkahā fasawwāhā

Yoruba Allāhu gbé àjà rẹ̀ ga sókè. Ó sì ṣe é ní pípé tó gún régé.

Verse 29

وَأَغْطَشَ لَيْلَهَا وَأَخْرَجَ ضُحَىٰهَا

Transliteration wa-aghṭasha laylahā wa-akhraja ḍuḥāhā

Yoruba Ó ṣe òru rẹ̀ ní dúdú. Ó sì fa ìyálẹ̀ta rẹ̀ yọ jáde.

Verse 30

وَٱلْأَرْضَ بَعْدَ ذَٰلِكَ دَحَىٰهَآ

Transliteration wal-arḍa baʿda dhālika daḥāhā

Yoruba Àti ilẹ̀, Ó tẹ́ ẹ pẹrẹsẹ lẹ́yìn ìyẹn.1

Verse 31

أَخْرَجَ مِنْهَا مَآءَهَا وَمَرْعَىٰهَا

Transliteration akhraja min'hā māahā wamarʿāhā

Yoruba Ó mú omi rẹ̀ àti irúgbìn rẹ̀ jáde láti inú rẹ̀.

Verse 32

وَٱلْجِبَالَ أَرْسَىٰهَا

Transliteration wal-jibāla arsāhā

Yoruba Àti àwọn àpáta, Ó fi ìdí wọn múlẹ̀ ṣinṣin.

Verse 33

مَتَـٰعًا لَّكُمْ وَلِأَنْعَـٰمِكُمْ

Transliteration matāʿan lakum wali-anʿāmikum

Yoruba Ìgbádùn ni fún yín àti fún àwọn ẹran-ọ̀sìn yín.

Verse 34

فَإِذَا جَآءَتِ ٱلطَّآمَّةُ ٱلْكُبْرَىٰ

Transliteration fa-idhā jāati l-ṭāmatu l-kub'rā

Yoruba Ṣùgbọ́n nígbà tí ìparun ńlá bá dé,

Verse 35

يَوْمَ يَتَذَكَّرُ ٱلْإِنسَـٰنُ مَا سَعَىٰ

Transliteration yawma yatadhakkaru l-insānu mā saʿā

Yoruba ní ọjọ́ tí ènìyàn yóò rántí ohun tó ṣe níṣẹ́.

Verse 36

وَبُرِّزَتِ ٱلْجَحِيمُ لِمَن يَرَىٰ

Transliteration waburrizati l-jaḥīmu liman yarā

Yoruba Wọ́n sì máa fi Iná hàn kedere fún (gbogbo) ẹni tó ríran.

Verse 37

فَأَمَّا مَن طَغَىٰ

Transliteration fa-ammā man ṭaghā

Yoruba Nítorí náà, ní ti ẹni tó tayọ ẹnu-ààlà,

Verse 38

وَءَاثَرَ ٱلْحَيَوٰةَ ٱلدُّنْيَا

Transliteration waāthara l-ḥayata l-dun'yā

Yoruba tí ó tún gbé àjùlọ fún ìṣẹ̀mí ayé,

Verse 39

فَإِنَّ ٱلْجَحِيمَ هِىَ ٱلْمَأْوَىٰ

Transliteration fa-inna l-jaḥīma hiya l-mawā

Yoruba dájúdájú iná Jẹhīm, òhun ni ibùgbé (rẹ̀).

Verse 40

وَأَمَّا مَنْ خَافَ مَقَامَ رَبِّهِۦ وَنَهَى ٱلنَّفْسَ عَنِ ٱلْهَوَىٰ

Transliteration wa-ammā man khāfa maqāma rabbihi wanahā l-nafsa ʿani l-hawā

Yoruba Ní ti ẹni tí ó páyà ìdúró níwájú Olúwa rẹ̀, tí ó tún kọ ìfẹ́-inú fún ẹ̀mí (ara rẹ̀),

Verse 41

فَإِنَّ ٱلْجَنَّةَ هِىَ ٱلْمَأْوَىٰ

Transliteration fa-inna l-janata hiya l-mawā

Yoruba dájúdájú Ọgbà Ìdẹ̀ra, òhun ni ibùgbé (rẹ̀).

Verse 42

يَسْـَٔلُونَكَ عَنِ ٱلسَّاعَةِ أَيَّانَ مُرْسَىٰهَا

Transliteration yasalūnaka ʿani l-sāʿati ayyāna mur'sāhā

Yoruba Wọ́n ń bi ọ́ léèrè nípa Àkókò náà pé: “Ìgbà wo l’ó máa ṣẹlẹ̀?”

Verse 43

فِيمَ أَنتَ مِن ذِكْرَىٰهَآ

Transliteration fīma anta min dhik'rāhā

Yoruba Níbo ni ìwọ wà sí ìmọ̀ rẹ̀ ná?1

Verse 44

إِلَىٰ رَبِّكَ مُنتَهَىٰهَآ

Transliteration ilā rabbika muntahāhā

Yoruba Ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ ni òpin ìmọ̀ nípa rẹ̀ wà.

Verse 45

إِنَّمَآ أَنتَ مُنذِرُ مَن يَخْشَىٰهَا

Transliteration innamā anta mundhiru man yakhshāhā

Yoruba Ìwọ kúkú ni olùkìlọ̀ fún ẹni tó ń páyà rẹ̀.

Verse 46

كَأَنَّهُمْ يَوْمَ يَرَوْنَهَا لَمْ يَلْبَثُوٓا۟ إِلَّا عَشِيَّةً أَوْ ضُحَىٰهَا

Transliteration ka-annahum yawma yarawnahā lam yalbathū illā ʿashiyyatan aw ḍuḥāhā

Yoruba Ní ọjọ́ tí wọ́n máa rí i, wọn máa dà bí ẹni pé wọn kò gbé ilé ayé tayọ ìrọ̀lẹ́ tàbí ìyálẹ̀ta (ọjọ́) kan.

Read Surah An-Nazi'at in another language

All languages

All 114 surahs in Yoruba: the Qur’an in Yoruba.

Learn it in MyDugsi

Yoruba translation: Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni, from Quran.com. Transliteration: Quran.com. Recitation: Mishary Alafasy, from EveryAyah.com. MyDugsi is a learning aid, not a replacement for a qualified teacher.