Surah Al-Waqi'ah in Yoruba: translation and audio
Surah 56 · الواقعة · The Inevitable · 96 verses
Surah Al-Waqi'ah verse by verse: the Arabic with a recitation you can repeat, the transliteration, and the Yoruba translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni. For the meaning of every word, see Surah Al-Waqi'ah word by word in English.
Verse 1
إِذَا وَقَعَتِ ٱلْوَاقِعَةُ
Transliteration idhā waqaʿati l-wāqiʿatu
Yoruba Nígbà tí Ìṣẹ̀lẹ̀ (Àjíǹde) bá ṣẹlẹ̀,
Verse 2
لَيْسَ لِوَقْعَتِهَا كَاذِبَةٌ
Transliteration laysa liwaqʿatihā kādhibatun
Yoruba - kò sí irọ́ kan nípa ìṣẹ̀lẹ̀ rẹ̀-
Verse 3
خَافِضَةٌ رَّافِعَةٌ
Transliteration khāfiḍatun rāfiʿatun
Yoruba ó máa mú (àwọn kan) wálẹ̀ (sínú Iná), ó sì máa gbé (àwọn kan) sókè (nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra).
Verse 4
إِذَا رُجَّتِ ٱلْأَرْضُ رَجًّا
Transliteration idhā rujjati l-arḍu rajjan
Yoruba Nígbà tí wọ́n bá mi ilẹ̀ tìtì ní mímìtìtì,
Verse 5
وَبُسَّتِ ٱلْجِبَالُ بَسًّا
Transliteration wabussati l-jibālu bassan
Yoruba àti nígbà tí Wọ́n bá fọ́ àwọn àpáta ní fífọ́ wómúwómú,
Verse 6
فَكَانَتْ هَبَآءً مُّنۢبَثًّا
Transliteration fakānat habāan munbathan
Yoruba - wọ́n sì máa di eruku àfẹ́dànù -
Verse 7
وَكُنتُمْ أَزْوَٰجًا ثَلَـٰثَةً
Transliteration wakuntum azwājan thalāthatan
Yoruba ẹ̀yin sì máa jẹ́ oríṣi mẹ́ta.1
Verse 8
فَأَصْحَـٰبُ ٱلْمَيْمَنَةِ مَآ أَصْحَـٰبُ ٱلْمَيْمَنَةِ
Transliteration fa-aṣḥābu l-maymanati mā aṣḥābu l-maymanati
Yoruba Àwọn èrò ọwọ́ ọ̀tún, kí ni (ó máa ti dára tó fún) àwọn èrò ọwọ́ ọ̀tún?
Verse 9
وَأَصْحَـٰبُ ٱلْمَشْـَٔمَةِ مَآ أَصْحَـٰبُ ٱلْمَشْـَٔمَةِ
Transliteration wa-aṣḥābu l-mashamati mā aṣḥābu l-mashamati
Yoruba Àwọn èrò ọwọ́ òsì, kí ni (ó máa ti burú tó fún) àwọn èrò ọwọ́ òsì?
Verse 10
وَٱلسَّـٰبِقُونَ ٱلسَّـٰبِقُونَ
Transliteration wal-sābiqūna l-sābiqūna
Yoruba Àwọn aṣíwájú sì ni àwọn aṣíwájú.
Verse 11
أُو۟لَـٰٓئِكَ ٱلْمُقَرَّبُونَ
Transliteration ulāika l-muqarabūna
Yoruba Àwọn wọ̀nyẹn ni alásùn-únmọ́ (Allāhu)
Verse 12
فِى جَنَّـٰتِ ٱلنَّعِيمِ
Transliteration fī jannāti l-naʿīmi
Yoruba nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra.
Verse 13
ثُلَّةٌ مِّنَ ٱلْأَوَّلِينَ
Transliteration thullatun mina l-awalīna
Yoruba Wọ́n pọ̀ nínú àwọn ẹni àkọ́kọ́.
Verse 14
وَقَلِيلٌ مِّنَ ٱلْـَٔاخِرِينَ
Transliteration waqalīlun mina l-ākhirīna
Yoruba Wọ́n sì kéré nínú àwọn ẹni Ìkẹ́yìn.
Verse 15
عَلَىٰ سُرُرٍ مَّوْضُونَةٍ
Transliteration ʿalā sururin mawḍūnatin
Yoruba (Wọn yóò wà) lórí ìtẹ́ tí wọ́n fi góòlù hun.
Verse 16
مُّتَّكِـِٔينَ عَلَيْهَا مُتَقَـٰبِلِينَ
Transliteration muttakiīna ʿalayhā mutaqābilīna
Yoruba Wọn yóò rọ̀gbọ̀kú sórí rẹ̀, wọn sì máa dojú kọra wọn.
Verse 17
يَطُوفُ عَلَيْهِمْ وِلْدَٰنٌ مُّخَلَّدُونَ
Transliteration yaṭūfu ʿalayhim wil'dānun mukhalladūna
Yoruba Àwọn ọ̀dọ́kùnrin tí kò níí darúgbó yó sì máa lọ bọ̀ láààrin wọn
Verse 18
بِأَكْوَابٍ وَأَبَارِيقَ وَكَأْسٍ مِّن مَّعِينٍ
Transliteration bi-akwābin wa-abārīqa wakasin min maʿīnin
Yoruba pẹ̀lú àwọn ife omi, ohun ìrọmi fẹ̀ǹfẹ̀ àti ife ọtí aládùn láti inú odò kan tó ń ṣàn (káà kiri ọ̀dọ̀ wọn).
Verse 19
لَّا يُصَدَّعُونَ عَنْهَا وَلَا يُنزِفُونَ
Transliteration lā yuṣaddaʿūna ʿanhā walā yunzifūna
Yoruba Kò níí fọ́ wọn lórí; kò sì níí mú wọn húnrìrà.
Verse 20
وَفَـٰكِهَةٍ مِّمَّا يَتَخَيَّرُونَ
Transliteration wafākihatin mimmā yatakhayyarūna
Yoruba Èso tí wọn yóò máa ṣẹ̀ṣà nínú rẹ̀ (tún wà fún wọn).
Verse 21
وَلَحْمِ طَيْرٍ مِّمَّا يَشْتَهُونَ
Transliteration walaḥmi ṭayrin mimmā yashtahūna
Yoruba Àti ẹran ẹyẹ, èyí tí wọ́n ń fẹ́ (yó wà fún wọn).
Verse 22
وَحُورٌ عِينٌ
Transliteration waḥūrun ʿīnun
Yoruba Àwọn obìnrin ẹlẹ́yinjú ẹgẹ́ (tún wà fún wọn).
Verse 23
كَأَمْثَـٰلِ ٱللُّؤْلُؤِ ٱلْمَكْنُونِ
Transliteration ka-amthāli l-lu'lu-i l-maknūni
Yoruba Wọ́n dà bí àlúùúlù (òkúta olówó-iye-bíye) tí wọ́n fi pamọ́ sínú apó rẹ̀.
Verse 24
جَزَآءًۢ بِمَا كَانُوا۟ يَعْمَلُونَ
Transliteration jazāan bimā kānū yaʿmalūna
Yoruba (Ìwọ̀nyí ni) ẹ̀san fún ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́.
Verse 25
لَا يَسْمَعُونَ فِيهَا لَغْوًا وَلَا تَأْثِيمًا
Transliteration lā yasmaʿūna fīhā laghwan walā tathīman
Yoruba Wọn kò níí gbọ́ ìsọkúsọ àti ọ̀rọ̀ ẹ̀ṣẹ̀ nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra.
Verse 26
إِلَّا قِيلًا سَلَـٰمًا سَلَـٰمًا
Transliteration illā qīlan salāman salāman
Yoruba Àyàfi ọ̀rọ̀ àlàáfíà, àlàáfíà.
Verse 27
وَأَصْحَـٰبُ ٱلْيَمِينِ مَآ أَصْحَـٰبُ ٱلْيَمِينِ
Transliteration wa-aṣḥābu l-yamīni mā aṣḥābu l-yamīni
Yoruba Àwọn èrò ọwọ́ ọtún, kí ni (ó máa ti dára tó fún) àwọn èrò ọwọ́ ọtún?
Verse 28
فِى سِدْرٍ مَّخْضُودٍ
Transliteration fī sid'rin makhḍūdin
Yoruba (Wọn yóò wà) ní ìdí igi tí kò ní ẹ̀gún,
Verse 29
وَطَلْحٍ مَّنضُودٍ
Transliteration waṭalḥin manḍūdin
Yoruba àti ọ̀gẹ̀dẹ̀ tó so jìgbìnnì,
Verse 30
وَظِلٍّ مَّمْدُودٍ
Transliteration waẓillin mamdūdin
Yoruba àti ibòji tó gbòòrò,
Verse 31
وَمَآءٍ مَّسْكُوبٍ
Transliteration wamāin maskūbin
Yoruba àti omi tó ń ṣàn láì dáwọ́ dúró,
Verse 32
وَفَـٰكِهَةٍ كَثِيرَةٍ
Transliteration wafākihatin kathīratin
Yoruba àti ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ èso,
Verse 33
لَّا مَقْطُوعَةٍ وَلَا مَمْنُوعَةٍ
Transliteration lā maqṭūʿatin walā mamnūʿatin
Yoruba tí kò níí já (ní ọ̀dọ̀ wọn), kò sì níí dèèwọ̀ (fún wọn).
Verse 34
وَفُرُشٍ مَّرْفُوعَةٍ
Transliteration wafurushin marfūʿatin
Yoruba (Wọ́n máa wà lórí) ìtẹ́ tí wọ́n gbé sókè.
Verse 35
إِنَّآ أَنشَأْنَـٰهُنَّ إِنشَآءً
Transliteration innā anshanāhunna inshāan
Yoruba Dájúdájú Àwa dá (àwọn obìnrin Ọgbà Ìdẹ̀ra) ní ẹ̀dá kan (tó yàtọ̀ sí tayé).
Verse 36
فَجَعَلْنَـٰهُنَّ أَبْكَارًا
Transliteration fajaʿalnāhunna abkāran
Yoruba A sì ṣe wọ́n ní wúńdíá,
Verse 37
عُرُبًا أَتْرَابًا
Transliteration ʿuruban atrāban
Yoruba olólùfẹ́ ọkọ. Wọ́n sì dọ́gba ní ọjọ́ orí.
Verse 38
لِّأَصْحَـٰبِ ٱلْيَمِينِ
Transliteration li-aṣḥābi l-yamīni
Yoruba (Wọ́n wà) fún àwọn èrò ọwọ́ ọ̀tún.
Verse 39
ثُلَّةٌ مِّنَ ٱلْأَوَّلِينَ
Transliteration thullatun mina l-awalīna
Yoruba Wọ́n pọ̀ nínú àwọn ẹni àkọ́kọ́.
Verse 40
وَثُلَّةٌ مِّنَ ٱلْـَٔاخِرِينَ
Transliteration wathullatun mina l-ākhirīna
Yoruba Wọ́n tún pọ̀ nínú àwọn ẹni Ìkẹ́yìn.1
Verse 41
وَأَصْحَـٰبُ ٱلشِّمَالِ مَآ أَصْحَـٰبُ ٱلشِّمَالِ
Transliteration wa-aṣḥābu l-shimāli mā aṣḥābu l-shimāli
Yoruba Àwọn èrò ọwọ́ òsì, kí ni (ó máa ti burú tó fún) àwọn èrò ọwọ́ òsì?
Verse 42
فِى سَمُومٍ وَحَمِيمٍ
Transliteration fī samūmin waḥamīmin
Yoruba (Wọn yóò wà) nínú atẹ́gùn gbígbóná (iná) àti omi tó gbóná parí,
Verse 43
وَظِلٍّ مِّن يَحْمُومٍ
Transliteration waẓillin min yaḥmūmin
Yoruba àti ní abẹ́ ibòji eléèéfín dúdú,
Verse 44
لَّا بَارِدٍ وَلَا كَرِيمٍ
Transliteration lā bāridin walā karīmin
Yoruba kò tutù, kò sì dára.
Verse 45
إِنَّهُمْ كَانُوا۟ قَبْلَ ذَٰلِكَ مُتْرَفِينَ
Transliteration innahum kānū qabla dhālika mut'rafīna
Yoruba Dájúdájú wọ́n ti jẹ́ onígbẹdẹmukẹ ṣíwájú ìyẹn.
Verse 46
وَكَانُوا۟ يُصِرُّونَ عَلَى ٱلْحِنثِ ٱلْعَظِيمِ
Transliteration wakānū yuṣirrūna ʿalā l-ḥinthi l-ʿaẓīmi
Yoruba Wọ́n sì máa ń ṣoríkunkun lórí ẹ̀ṣẹ̀ ńlá.
Verse 47
وَكَانُوا۟ يَقُولُونَ أَئِذَا مِتْنَا وَكُنَّا تُرَابًا وَعِظَـٰمًا أَءِنَّا لَمَبْعُوثُونَ
Transliteration wakānū yaqūlūna a-idhā mit'nā wakunnā turāban waʿiẓāman a-innā lamabʿūthūna
Yoruba Wọ́n sì máa ń wí pé: “Ṣé nígbà tí a bá di òkú, tí a sì di erùpẹ̀ àti egungun, ǹjẹ́ Wọn yóò tún gbé wa dìde ni?
Verse 48
أَوَءَابَآؤُنَا ٱلْأَوَّلُونَ
Transliteration awaābāunā l-awalūna
Yoruba Ṣé àti àwọn bàbá wa, àwọn ẹni àkọ́kọ́?”
Verse 49
قُلْ إِنَّ ٱلْأَوَّلِينَ وَٱلْـَٔاخِرِينَ
Transliteration qul inna l-awalīna wal-ākhirīna
Yoruba Sọ pé: “Dájúdájú àwọn ẹni àkọ́kọ́ àti àwọn ẹni Ìkẹ́yìn,
Verse 50
لَمَجْمُوعُونَ إِلَىٰ مِيقَـٰتِ يَوْمٍ مَّعْلُومٍ
Transliteration lamajmūʿūna ilā mīqāti yawmin maʿlūmin
Yoruba dájúdájú A óò kó wọn jọ papọ̀ ní àkókò ọjọ́ kan tí A ti mọ̀.”
Verse 51
ثُمَّ إِنَّكُمْ أَيُّهَا ٱلضَّآلُّونَ ٱلْمُكَذِّبُونَ
Transliteration thumma innakum ayyuhā l-ḍālūna l-mukadhibūna
Yoruba Lẹ́yìn náà, dájúdájú ẹ̀yin olùṣìnà, olùpe-òdodo-nírọ́,
Verse 52
لَـَٔاكِلُونَ مِن شَجَرٍ مِّن زَقُّومٍ
Transliteration laākilūna min shajarin min zaqqūmin
Yoruba dájúdájú ẹ̀yin máa jẹ nínú igi zaƙƙūm (igi iwọ).
Verse 53
فَمَالِـُٔونَ مِنْهَا ٱلْبُطُونَ
Transliteration famāliūna min'hā l-buṭūna
Yoruba Ikùn yín sì máa kún bámúbámú fún (jíjẹ) igi náà.
Verse 54
فَشَـٰرِبُونَ عَلَيْهِ مِنَ ٱلْحَمِيمِ
Transliteration fashāribūna ʿalayhi mina l-ḥamīmi
Yoruba Ẹ̀yin yó sì máa mu omi tó gbóná parí lé e lórí.
Verse 55
فَشَـٰرِبُونَ شُرْبَ ٱلْهِيمِ
Transliteration fashāribūna shur'ba l-hīmi
Yoruba Ẹ̀yin yóò máa mu ún ní ìmumi ràkúnmí tí òǹgbẹ ń gbẹ.
Verse 56
هَـٰذَا نُزُلُهُمْ يَوْمَ ٱلدِّينِ
Transliteration hādhā nuzuluhum yawma l-dīni
Yoruba Èyí ni n̄ǹkan àlejò wọn ní Ọjọ́ ẹ̀san.
Verse 57
نَحْنُ خَلَقْنَـٰكُمْ فَلَوْلَا تُصَدِّقُونَ
Transliteration naḥnu khalaqnākum falawlā tuṣaddiqūna
Yoruba Àwa l’A ṣẹ̀dá yín. Kí ni kò jẹ́ kí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo!
Verse 58
أَفَرَءَيْتُم مَّا تُمْنُونَ
Transliteration afara-aytum mā tum'nūna
Yoruba Ẹ sọ fún Mi nípa àtọ̀ tí ẹ̀ ń dà jáde (sínú àpòlùkẹ́),
Verse 59
ءَأَنتُمْ تَخْلُقُونَهُۥٓ أَمْ نَحْنُ ٱلْخَـٰلِقُونَ
Transliteration a-antum takhluqūnahu am naḥnu l-khāliqūna
Yoruba ṣé ẹ̀yin lẹ ṣẹ̀dá rẹ̀ ni tàbí Àwa l’A ṣẹ̀dá rẹ̀?
Verse 60
نَحْنُ قَدَّرْنَا بَيْنَكُمُ ٱلْمَوْتَ وَمَا نَحْنُ بِمَسْبُوقِينَ
Transliteration naḥnu qaddarnā baynakumu l-mawta wamā naḥnu bimasbūqīna
Yoruba Àwa l’A yan kádàrá (ọjọ́) ikú fún gbogbo yín. Àwa kò sì lè kágara
Verse 61
عَلَىٰٓ أَن نُّبَدِّلَ أَمْثَـٰلَكُمْ وَنُنشِئَكُمْ فِى مَا لَا تَعْلَمُونَ
Transliteration ʿalā an nubaddila amthālakum wanunshi-akum fī mā lā taʿlamūna
Yoruba láti yí irú yín padà (láti erùpẹ̀ sí alààyè), kí á sì tun yín dá (ní ọ̀tun) sínú ohun tí ẹ kò mọ̀.
Verse 62
وَلَقَدْ عَلِمْتُمُ ٱلنَّشْأَةَ ٱلْأُولَىٰ فَلَوْلَا تَذَكَّرُونَ
Transliteration walaqad ʿalim'tumu l-nashata l-ūlā falawlā tadhakkarūna
Yoruba Ẹ kúkú mọ ìṣẹ̀dá àkọ́kọ́ (pé láti ibi àìsí ni ẹ ti di alààyè), ẹ kò ṣe lo ìrántí?
Verse 63
أَفَرَءَيْتُم مَّا تَحْرُثُونَ
Transliteration afara-aytum mā taḥruthūna
Yoruba Ẹ sọ fún Mi nípa n̄ǹkan tí ẹ̀ ń gbìn sínú ilẹ̀,
Verse 64
ءَأَنتُمْ تَزْرَعُونَهُۥٓ أَمْ نَحْنُ ٱلزَّٰرِعُونَ
Transliteration a-antum tazraʿūnahu am naḥnu l-zāriʿūna
Yoruba ṣé ẹ̀yin l’ẹ̀ ń jẹ́ kí ó hù jáde tàbí Àwa l’À ń jẹ́ kí ó hù jáde?
Verse 65
لَوْ نَشَآءُ لَجَعَلْنَـٰهُ حُطَـٰمًا فَظَلْتُمْ تَفَكَّهُونَ
Transliteration law nashāu lajaʿalnāhu ḥuṭāman faẓaltum tafakkahūna
Yoruba Tí A bá fẹ́ ni, Àwa ìbá sọ ọ́ di gbígbẹ, ẹ̀yin yó sì máa ṣèèmọ̀ (tí ẹ óò máa ká àbámọ̀).
Verse 66
إِنَّا لَمُغْرَمُونَ
Transliteration innā lamugh'ramūna
Yoruba (Ẹ̀yin yó sì wí pé:) “Dájúdájú àwa ti di onígbèsè.”
Verse 67
بَلْ نَحْنُ مَحْرُومُونَ
Transliteration bal naḥnu maḥrūmūna
Yoruba (Àwọn mìíràn yó sì wí pé:) “Rárá o! Wọ́n ṣe ìkórè oko ní èèwọ̀ fún wa ni.”
Verse 68
أَفَرَءَيْتُمُ ٱلْمَآءَ ٱلَّذِى تَشْرَبُونَ
Transliteration afara-aytumu l-māa alladhī tashrabūna
Yoruba Ẹ sọ fún mi nípa omi tí ẹ̀ ń mu,
Verse 69
ءَأَنتُمْ أَنزَلْتُمُوهُ مِنَ ٱلْمُزْنِ أَمْ نَحْنُ ٱلْمُنزِلُونَ
Transliteration a-antum anzaltumūhu mina l-muz'ni am naḥnu l-munzilūna
Yoruba ṣé ẹ̀yin l’ẹ̀ ń sọ̀ ọ́ kalẹ̀ láti inú ẹ̀ṣújò ni tàbí Àwa l’À ń sọ̀ ọ́ kalẹ̀?
Verse 70
لَوْ نَشَآءُ جَعَلْنَـٰهُ أُجَاجًا فَلَوْلَا تَشْكُرُونَ
Transliteration law nashāu jaʿalnāhu ujājan falawlā tashkurūna
Yoruba Tí A bá fẹ́ ni, Àwa ìbá ṣe é ní omi tó móró. Ẹ ò ṣe máa dúpẹ́?
Verse 71
أَفَرَءَيْتُمُ ٱلنَّارَ ٱلَّتِى تُورُونَ
Transliteration afara-aytumu l-nāra allatī tūrūna
Yoruba Ẹ sọ fún Mi nípa iná tí ẹ̀ ń dá,
Verse 72
ءَأَنتُمْ أَنشَأْتُمْ شَجَرَتَهَآ أَمْ نَحْنُ ٱلْمُنشِـُٔونَ
Transliteration a-antum anshatum shajaratahā am naḥnu l-munshiūna
Yoruba ṣé ẹ̀yin l’ẹ ṣẹ̀dá igi rẹ̀ ni tàbí Àwa ni Aṣẹ̀dá?
Verse 73
نَحْنُ جَعَلْنَـٰهَا تَذْكِرَةً وَمَتَـٰعًا لِّلْمُقْوِينَ
Transliteration naḥnu jaʿalnāhā tadhkiratan wamatāʿan lil'muq'wīna
Yoruba Àwa ṣe iná ayé ní ìrántí (fún Iná ọ̀run) àti n̄ǹkan èlò fún àwọn onírìn-àjò.
Verse 74
فَسَبِّحْ بِٱسْمِ رَبِّكَ ٱلْعَظِيمِ
Transliteration fasabbiḥ bi-is'mi rabbika l-ʿaẓīmi
Yoruba Nítorí náà, ṣàfọ̀mọ́ fún orúkọ Olúwa rẹ, Atóbi.
Verse 75
۞ فَلَآ أُقْسِمُ بِمَوَٰقِعِ ٱلنُّجُومِ
Transliteration falā uq'simu bimawāqiʿi l-nujūmi
Yoruba Nítorí náà, Mò ń fi àwọn àyè tí ìkọ̀ọ̀kan gbólóhùn al-Ƙur’ān wà nínú sánmọ̀ búra.1
Verse 76
وَإِنَّهُۥ لَقَسَمٌ لَّوْ تَعْلَمُونَ عَظِيمٌ
Transliteration wa-innahu laqasamun law taʿlamūna ʿaẓīmun
Yoruba Dájúdájú ìbúra ńlá ni, tí ẹ bá mọ̀.
Verse 77
إِنَّهُۥ لَقُرْءَانٌ كَرِيمٌ
Transliteration innahu laqur'ānun karīmun
Yoruba Dájúdájú (al-Ƙur’ān) ni n̄ǹkan kíké alápọ̀n-ọ́nlé.
Verse 78
فِى كِتَـٰبٍ مَّكْنُونٍ
Transliteration fī kitābin maknūnin
Yoruba Ó wà nínú Tírà kan tí wọ́n ń fi ààbò bò (ìyẹn Laohul-Mahfūṭḥ).
Verse 79
لَّا يَمَسُّهُۥٓ إِلَّا ٱلْمُطَهَّرُونَ
Transliteration lā yamassuhu illā l-muṭaharūna
Yoruba Kò sí ẹni tó lè fọwọ́ kàn án (ní ọ̀dọ̀ Allāhu) àfi àwọn ẹni mímọ́ (ìyẹn, àwọn mọlāika).
Verse 80
تَنزِيلٌ مِّن رَّبِّ ٱلْعَـٰلَمِينَ
Transliteration tanzīlun min rabbi l-ʿālamīna
Yoruba Wọ́n sọ al-Ƙur’ān kalẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Olúwa gbogbo ẹ̀dá.
Verse 81
أَفَبِهَـٰذَا ٱلْحَدِيثِ أَنتُم مُّدْهِنُونَ
Transliteration afabihādhā l-ḥadīthi antum mud'hinūna
Yoruba Nítorí náà, ṣé ọ̀rọ̀ (al-Ƙur’ān) yìí l’ẹ̀ ń pè ní irọ́?
Verse 82
وَتَجْعَلُونَ رِزْقَكُمْ أَنَّكُمْ تُكَذِّبُونَ
Transliteration watajʿalūna riz'qakum annakum tukadhibūna
Yoruba Ẹ sì ń sọ ìdúpẹ́ arísìkí yín di pé dájúdájú ẹ̀ ń pe òdodo ní irọ́.1
Verse 83
فَلَوْلَآ إِذَا بَلَغَتِ ٱلْحُلْقُومَ
Transliteration falawlā idhā balaghati l-ḥul'qūma
Yoruba Kí ni ó máa ti rí (fún yín) nígbà tí ẹ̀mí (yín) bá dé ọ̀nà ọ̀fun,
Verse 84
وَأَنتُمْ حِينَئِذٍ تَنظُرُونَ
Transliteration wa-antum ḥīna-idhin tanẓurūna
Yoruba tí ẹ̀yin yó sì máa wò bọ̀ọ̀ nígbà yẹn?
Verse 85
وَنَحْنُ أَقْرَبُ إِلَيْهِ مِنكُمْ وَلَـٰكِن لَّا تُبْصِرُونَ
Transliteration wanaḥnu aqrabu ilayhi minkum walākin lā tub'ṣirūna
Yoruba Àwa sì súnmọ́ ọn ju ẹ̀yin lọ, ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò ríran.1
Verse 86
فَلَوْلَآ إِن كُنتُمْ غَيْرَ مَدِينِينَ
Transliteration falawlā in kuntum ghayra madīnīna
Yoruba Ẹ̀yin kò ṣe jẹ́ ẹni tí A ò níí gbẹ̀san lára rẹ̀,
Verse 87
تَرْجِعُونَهَآ إِن كُنتُمْ صَـٰدِقِينَ
Transliteration tarjiʿūnahā in kuntum ṣādiqīna
Yoruba kí ẹ sì dá (ẹ̀mí tí ó fẹ́ bọ́) padà, tí ẹ bá jẹ́ olódodo.
Verse 88
فَأَمَّآ إِن كَانَ مِنَ ٱلْمُقَرَّبِينَ
Transliteration fa-ammā in kāna mina l-muqarabīna
Yoruba Ní ti ẹni tí ó bá wà nínú àwọn alásùn-únmọ́ (Wa),
Verse 89
فَرَوْحٌ وَرَيْحَانٌ وَجَنَّتُ نَعِيمٍ
Transliteration farawḥun warayḥānun wajannatu naʿīmin
Yoruba ìsinmi, èsè tó dára àti Ọgbà Ìdẹ̀ra (ni tirẹ̀).
Verse 90
وَأَمَّآ إِن كَانَ مِنْ أَصْحَـٰبِ ٱلْيَمِينِ
Transliteration wa-ammā in kāna min aṣḥābi l-yamīni
Yoruba Ní ti ẹni tí ó bá wà nínú àwọn èrò ọwọ́ ọ̀tún,
Verse 91
فَسَلَـٰمٌ لَّكَ مِنْ أَصْحَـٰبِ ٱلْيَمِينِ
Transliteration fasalāmun laka min aṣḥābi l-yamīni
Yoruba àlàáfíà ni fún ọ láààrin àwọn èrò ọwọ́ ọ̀tún.
Verse 92
وَأَمَّآ إِن كَانَ مِنَ ٱلْمُكَذِّبِينَ ٱلضَّآلِّينَ
Transliteration wa-ammā in kāna mina l-mukadhibīna l-ḍālīna
Yoruba Ní ti ẹni tí ó bá wà nínú àwọn olùpe-òdodo-nírọ́, àwọn olùṣìnà,
Verse 93
فَنُزُلٌ مِّنْ حَمِيمٍ
Transliteration fanuzulun min ḥamīmin
Yoruba n̄ǹkan àlejò (wọn) ni omi tó gbóná parí
Verse 94
وَتَصْلِيَةُ جَحِيمٍ
Transliteration wataṣliyatu jaḥīmin
Yoruba àti wíwọ inú iná Jẹhīm.
Verse 95
إِنَّ هَـٰذَا لَهُوَ حَقُّ ٱلْيَقِينِ
Transliteration inna hādhā lahuwa ḥaqqu l-yaqīni
Yoruba Dájúdájú èyí, òhun ni òdodo tó dájú.
Verse 96
فَسَبِّحْ بِٱسْمِ رَبِّكَ ٱلْعَظِيمِ
Transliteration fasabbiḥ bi-is'mi rabbika l-ʿaẓīmi
Yoruba Nítorí náà, ṣàfọ̀mọ́ fún orúkọ Olúwa rẹ, Atóbi.
Read Surah Al-Waqi'ah in another language
- English (word by word)
- Albanian
- Amazigh
- Amharic
- Assamese
- Azerbaijani
- Bambara
- Bangla
- Bosnian
- Bulgarian
- Chechen
- Chinese
- Czech
- Dari
- Dhivehi
- Dutch
- Finnish
- French
- German
- Gujarati
- Hausa
- Hebrew
- Hindi
- Indonesian
- Italian
- Japanese
- Kannada
- Kazakh
- Khmer
- Kinyarwanda
- Korean
- Kurdish
- Luganda
- Malay
- Malayalam
- Maranao
- Marathi
- Nepali
- Norwegian
- Oromo
- Pashto
- Persian
- Polish
- Portuguese
- Romanian
- Russian
- Sindhi
- Sinhala
- Somali
- Spanish
- Swahili
- Swedish
- Tagalog
- Tajik
- Tamil
- Tatar
- Telugu
- Thai
- Turkish
- Ukrainian
- Urdu
- Uyghur
- Uzbek
- Vietnamese
- Yao
All 114 surahs in Yoruba: the Qur’an in Yoruba.
Yoruba translation: Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni, from Quran.com. Transliteration: Quran.com. Recitation: Mishary Alafasy, from EveryAyah.com. MyDugsi is a learning aid, not a replacement for a qualified teacher.