MyDugsiStart learning

Surah An-Naba in Yoruba: translation and audio

Surah 78 · النبإ · The Tidings · 40 verses

Surah An-Naba verse by verse: the Arabic with a recitation you can repeat, the transliteration, and the Yoruba translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni. For the meaning of every word, see Surah An-Naba word by word in English.

Verse 1

عَمَّ يَتَسَآءَلُونَ

Transliteration ʿamma yatasāalūna

Yoruba Nípa kí ni wọ́n ń bíra wọn léèrè ná?

Verse 2

عَنِ ٱلنَّبَإِ ٱلْعَظِيمِ

Transliteration ʿani l-naba-i l-ʿaẓīmi

Yoruba Nípa ìró ìkọ̀kọ̀ ńlá ni,

Verse 3

ٱلَّذِى هُمْ فِيهِ مُخْتَلِفُونَ

Transliteration alladhī hum fīhi mukh'talifūna

Yoruba èyí tí wọ́n ń yapa-ẹnu lórí rẹ̀.

Verse 4

كَلَّا سَيَعْلَمُونَ

Transliteration kallā sayaʿlamūna

Yoruba Rárá! Wọ́n ń bọ̀ wá mọ̀.

Verse 5

ثُمَّ كَلَّا سَيَعْلَمُونَ

Transliteration thumma kallā sayaʿlamūna

Yoruba Lẹ́yìn náà, rárá sẹ́, wọ́n ń bọ̀ wá mọ̀.

Verse 6

أَلَمْ نَجْعَلِ ٱلْأَرْضَ مِهَـٰدًا

Transliteration alam najʿali l-arḍa mihādan

Yoruba Ǹjẹ́ Àwa kò ṣe ilẹ̀ ní ìtẹ́ bí,

Verse 7

وَٱلْجِبَالَ أَوْتَادًا

Transliteration wal-jibāla awtādan

Yoruba àti àwọn àpáta ní èèkàn (fún ilẹ̀)?

Verse 8

وَخَلَقْنَـٰكُمْ أَزْوَٰجًا

Transliteration wakhalaqnākum azwājan

Yoruba A sì ṣẹ̀dá yín ní oríṣiríṣi (akọ àti abo).

Verse 9

وَجَعَلْنَا نَوْمَكُمْ سُبَاتًا

Transliteration wajaʿalnā nawmakum subātan

Yoruba A ṣe oorun yín ní ìsinmi.

Verse 10

وَجَعَلْنَا ٱلَّيْلَ لِبَاسًا

Transliteration wajaʿalnā al-layla libāsan

Yoruba A tún ṣe alẹ́ ní ìbora.

Verse 11

وَجَعَلْنَا ٱلنَّهَارَ مَعَاشًا

Transliteration wajaʿalnā l-nahāra maʿāshan

Yoruba A tún ṣe ọ̀sán ní (àsìkò fún) wíwá ìjẹ-ìmu.

Verse 12

وَبَنَيْنَا فَوْقَكُمْ سَبْعًا شِدَادًا

Transliteration wabanaynā fawqakum sabʿan shidādan

Yoruba A tún mọ sánmọ̀ méje tó lágbára sókè yín.

Verse 13

وَجَعَلْنَا سِرَاجًا وَهَّاجًا

Transliteration wajaʿalnā sirājan wahhājan

Yoruba A tún ṣe òòrùn ní ìmọ́lẹ̀ tó ń tàn gbòlà.

Verse 14

وَأَنزَلْنَا مِنَ ٱلْمُعْصِرَٰتِ مَآءً ثَجَّاجًا

Transliteration wa-anzalnā mina l-muʿ'ṣirāti māan thajjājan

Yoruba Àti pé A sọ omi tó ń bọ́ tẹ̀léra wọn kalẹ̀ láti inú àwọn ẹ̀ṣújò

Verse 15

لِّنُخْرِجَ بِهِۦ حَبًّا وَنَبَاتًا

Transliteration linukh'rija bihi ḥabban wanabātan

Yoruba nítorí kí Á lè fi mú kóró èso àti irúgbìn jáde

Verse 16

وَجَنَّـٰتٍ أَلْفَافًا

Transliteration wajannātin alfāfan

Yoruba pẹ̀lú àwọn ọgbà tó kún digbí fún n̄ǹkan oko.

Verse 17

إِنَّ يَوْمَ ٱلْفَصْلِ كَانَ مِيقَـٰتًا

Transliteration inna yawma l-faṣli kāna mīqātan

Yoruba Dájúdájú ọjọ́ ìpínyà, ó ní gbèdéke àkókò kan.

Verse 18

يَوْمَ يُنفَخُ فِى ٱلصُّورِ فَتَأْتُونَ أَفْوَاجًا

Transliteration yawma yunfakhu fī l-ṣūri fatatūna afwājan

Yoruba (Ìyẹn ni) ọjọ́ tí wọ́n á fọn fèrè oníwo fún àjíǹde. Ẹ̀yin yó sì máa wá níjọ-níjọ.

Verse 19

وَفُتِحَتِ ٱلسَّمَآءُ فَكَانَتْ أَبْوَٰبًا

Transliteration wafutiḥati l-samāu fakānat abwāban

Yoruba Wọ́n sì máa ṣí sánmọ̀ sílẹ̀. Ó sì máa di àwọn ìlẹ̀kùn.

Verse 20

وَسُيِّرَتِ ٱلْجِبَالُ فَكَانَتْ سَرَابًا

Transliteration wasuyyirati l-jibālu fakānat sarāban

Yoruba Wọ́n máa mú àwọn àpáta rìn (bọ́ sí àyè mìíràn). Ó sì máa di ahúnpeéná.

Verse 21

إِنَّ جَهَنَّمَ كَانَتْ مِرْصَادًا

Transliteration inna jahannama kānat mir'ṣādan

Yoruba Dájúdájú iná Jahanamọ, ó lúgọ sílẹ̀ lójú ọ̀nà.

Verse 22

لِّلطَّـٰغِينَ مَـَٔابًا

Transliteration lilṭṭāghīna maāban

Yoruba (Ó jẹ́) ibùgbé fún àwọn alákọyọ.

Verse 23

لَّـٰبِثِينَ فِيهَآ أَحْقَابًا

Transliteration lābithīna fīhā aḥqāban

Yoruba Wọn yóò máa gbé inú rẹ̀ fún ìgbà gbọọrọ.

Verse 24

لَّا يَذُوقُونَ فِيهَا بَرْدًا وَلَا شَرَابًا

Transliteration lā yadhūqūna fīhā bardan walā sharāban

Yoruba Wọn kò níí rí ìtura tàbí ohun mímu kan tọ́wò nínú rẹ̀,

Verse 25

إِلَّا حَمِيمًا وَغَسَّاقًا

Transliteration illā ḥamīman waghassāqan

Yoruba àyàfi omi tó gbóná parí àti àwọnúwẹ̀jẹ̀.

Verse 26

جَزَآءً وِفَاقًا

Transliteration jazāan wifāqan

Yoruba (Ó jẹ́) ẹ̀san tó ṣe wẹ́kú (iṣẹ́ wọn).

Verse 27

إِنَّهُمْ كَانُوا۟ لَا يَرْجُونَ حِسَابًا

Transliteration innahum kānū lā yarjūna ḥisāban

Yoruba Dájúdájú wọn kì í retí ìṣírò-iṣẹ́.

Verse 28

وَكَذَّبُوا۟ بِـَٔايَـٰتِنَا كِذَّابًا

Transliteration wakadhabū biāyātinā kidhāban

Yoruba Wọ́n sì pe àwọn āyah Wa ní irọ́ gan-an.

Verse 29

وَكُلَّ شَىْءٍ أَحْصَيْنَـٰهُ كِتَـٰبًا

Transliteration wakulla shayin aḥṣaynāhu kitāban

Yoruba Gbogbo n̄ǹkan sì ni A ti ṣe àkọsílẹ̀ rẹ̀ sínú Tírà kan.

Verse 30

فَذُوقُوا۟ فَلَن نَّزِيدَكُمْ إِلَّا عَذَابًا

Transliteration fadhūqū falan nazīdakum illā ʿadhāban

Yoruba Nítorí náà, ẹ tọ́ (ìyà) wò. A ò sì níí ṣe àlékún kan fún yín bí kò ṣe ìyà.

Verse 31

إِنَّ لِلْمُتَّقِينَ مَفَازًا

Transliteration inna lil'muttaqīna mafāzan

Yoruba Dájúdájú ìgbàlà wà fún àwọn olùbẹ̀rù (Allāhu).

Verse 32

حَدَآئِقَ وَأَعْنَـٰبًا

Transliteration ḥadāiqa wa-aʿnāban

Yoruba Àwọn ọgbà oko àti èso àjàrà,

Verse 33

وَكَوَاعِبَ أَتْرَابًا

Transliteration wakawāʿiba atrāban

Yoruba àti àwọn ọlọ́mọge, tí wọn kò júra wọn lọ lọ́jọ́-orí,

Verse 34

وَكَأْسًا دِهَاقًا

Transliteration wakasan dihāqan

Yoruba àti ife ọtí tó kún dẹnu (ni ẹ̀san wọn).

Verse 35

لَّا يَسْمَعُونَ فِيهَا لَغْوًا وَلَا كِذَّٰبًا

Transliteration lā yasmaʿūna fīhā laghwan walā kidhāban

Yoruba Wọn kò níí gbọ́ ìsọkúsọ àti ọ̀rọ̀ irọ́ nínú rẹ̀.

Verse 36

جَزَآءً مِّن رَّبِّكَ عَطَآءً حِسَابًا

Transliteration jazāan min rabbika ʿaṭāan ḥisāban

Yoruba (Ó jẹ́) ẹ̀san láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ, (ó sì jẹ́) ọrẹ ní ìbámu sí ìṣírò-iṣẹ́ (wọn).

Verse 37

رَّبِّ ٱلسَّمَـٰوَٰتِ وَٱلْأَرْضِ وَمَا بَيْنَهُمَا ٱلرَّحْمَـٰنِ ۖ لَا يَمْلِكُونَ مِنْهُ خِطَابًا

Transliteration rabbi l-samāwāti wal-arḍi wamā baynahumā l-raḥmāni lā yamlikūna min'hu khiṭāban

Yoruba (Ẹsan náà wá láti ọ̀dọ̀) Olúwa àwọn sánmọ̀, ilẹ̀ àti ohun tó wà láààrin méjèèjì, Àjọkẹ́-ayé. Wọn kò sì ní ìkápá ọ̀rọ̀ lọ́dọ̀ Rẹ̀.

Verse 38

يَوْمَ يَقُومُ ٱلرُّوحُ وَٱلْمَلَـٰٓئِكَةُ صَفًّا ۖ لَّا يَتَكَلَّمُونَ إِلَّا مَنْ أَذِنَ لَهُ ٱلرَّحْمَـٰنُ وَقَالَ صَوَابًا

Transliteration yawma yaqūmu l-rūḥu wal-malāikatu ṣaffan lā yatakallamūna illā man adhina lahu l-raḥmānu waqāla ṣawāban

Yoruba Ọjọ́ tí mọlāika Jibrīl àti àwọn mọlāika (mìíràn) yóò dúró ní ọ̀wọ̀ọ̀wọ́. Wọn kò sì níí sọ̀rọ̀ àfi ẹni tí Àjọké-ayé bá yọ̀ǹda fún. Onítọ̀ún sì máa sọ̀rọ̀ tó máa ṣe wẹ́kú.

Verse 39

ذَٰلِكَ ٱلْيَوْمُ ٱلْحَقُّ ۖ فَمَن شَآءَ ٱتَّخَذَ إِلَىٰ رَبِّهِۦ مَـَٔابًا

Transliteration dhālika l-yawmu l-ḥaqu faman shāa ittakhadha ilā rabbihi maāban

Yoruba Ìyẹn ni ọjọ́ òdodo. Nítorí náà, ẹni tí ó bá fẹ́ kí ó mú ọ̀nà tó máa gbà ṣẹ́rí padà sí ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ̀ pọ̀n (ní ti ìronúpìwàdà).

Verse 40

إِنَّآ أَنذَرْنَـٰكُمْ عَذَابًا قَرِيبًا يَوْمَ يَنظُرُ ٱلْمَرْءُ مَا قَدَّمَتْ يَدَاهُ وَيَقُولُ ٱلْكَافِرُ يَـٰلَيْتَنِى كُنتُ تُرَٰبًۢا

Transliteration innā andharnākum ʿadhāban qarīban yawma yanẓuru l-maru mā qaddamat yadāhu wayaqūlu l-kāfiru yālaytanī kuntu turāban

Yoruba Dájúdájú A fi ìyà tó súnmọ́ ṣe ìkìlọ̀ fún yín. Ọjọ́ tí ènìyàn yóò máa wo ohun tí ó tì síwájú, aláìgbàgbọ́ yó sì wí pé: “Yéè, èmi ìbá sì jẹ́ erùpẹ̀, (èmi ìbá là nínú ìyà).”

Read Surah An-Naba in another language

All languages

All 114 surahs in Yoruba: the Qur’an in Yoruba.

Learn it in MyDugsi

Yoruba translation: Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni, from Quran.com. Transliteration: Quran.com. Recitation: Mishary Alafasy, from EveryAyah.com. MyDugsi is a learning aid, not a replacement for a qualified teacher.