MyDugsiStart learning

Surah Al-Qiyamah in Yoruba: translation and audio

Surah 75 · القيامة · The Resurrection · 40 verses

Surah Al-Qiyamah verse by verse: the Arabic with a recitation you can repeat, the transliteration, and the Yoruba translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni. For the meaning of every word, see Surah Al-Qiyamah word by word in English.

Verse 1

لَآ أُقْسِمُ بِيَوْمِ ٱلْقِيَـٰمَةِ

Transliteration lā uq'simu biyawmi l-qiyāmati

Yoruba Èmi (Allāhu) ń fi Ọjọ́ Àjíǹde búra.

Verse 2

وَلَآ أُقْسِمُ بِٱلنَّفْسِ ٱللَّوَّامَةِ

Transliteration walā uq'simu bil-nafsi l-lawāmati

Yoruba Mo tún ń fi ẹ̀mí tó máa dá ara rẹ̀ ní ẹ̀bi búra.

Verse 3

أَيَحْسَبُ ٱلْإِنسَـٰنُ أَلَّن نَّجْمَعَ عِظَامَهُۥ

Transliteration ayaḥsabu l-insānu allan najmaʿa ʿiẓāmahu

Yoruba Ṣé ènìyàn lérò pé A kò níí kó àwọn eegun rẹ̀ jọ ni?

Verse 4

بَلَىٰ قَـٰدِرِينَ عَلَىٰٓ أَن نُّسَوِّىَ بَنَانَهُۥ

Transliteration balā qādirīna ʿalā an nusawwiya banānahu

Yoruba Bẹ́ẹ̀ ni A sì lágbára láti to eegun ọmọníka rẹ̀ dọ́gba

Verse 5

بَلْ يُرِيدُ ٱلْإِنسَـٰنُ لِيَفْجُرَ أَمَامَهُۥ

Transliteration bal yurīdu l-insānu liyafjura amāmahu

Yoruba Rárá ènìyàn fẹ́ máa ṣe aburú lọ bẹ́ẹ̀ nínú ìṣẹ̀mí ayé rẹ̀

Verse 6

يَسْـَٔلُ أَيَّانَ يَوْمُ ٱلْقِيَـٰمَةِ

Transliteration yasalu ayyāna yawmu l-qiyāmati

Yoruba ni ó fi ń bèèrè pé: “Ìgbà wo ni Ọjọ́ Àjíǹde?”

Verse 7

فَإِذَا بَرِقَ ٱلْبَصَرُ

Transliteration fa-idhā bariqa l-baṣaru

Yoruba Nígbà tí ojú bá rí ìdààmú tó sì yà sílẹ̀ tí kò lè padé,

Verse 8

وَخَسَفَ ٱلْقَمَرُ

Transliteration wakhasafa l-qamaru

Yoruba àti (nígbà) tí òṣùpá bá wọ̀ọ̀kùn,

Verse 9

وَجُمِعَ ٱلشَّمْسُ وَٱلْقَمَرُ

Transliteration wajumiʿa l-shamsu wal-qamaru

Yoruba àti (nígbà) tí wọ́n bá pa òòrùn àti òṣùpá pọ̀ mọ́ra wọn tí ìmọ́lẹ̀ méjèèjì pòóró,

Verse 10

يَقُولُ ٱلْإِنسَـٰنُ يَوْمَئِذٍ أَيْنَ ٱلْمَفَرُّ

Transliteration yaqūlu l-insānu yawma-idhin ayna l-mafaru

Yoruba ènìyàn yóò wí ní ọjọ́ yẹn pé: “Níbo ni ibùsásí wà?”

Verse 11

كَلَّا لَا وَزَرَ

Transliteration kallā lā wazara

Yoruba Rárá, kò sí ibùsásí.

Verse 12

إِلَىٰ رَبِّكَ يَوْمَئِذٍ ٱلْمُسْتَقَرُّ

Transliteration ilā rabbika yawma-idhin l-mus'taqaru

Yoruba Ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ ni ibùdúró ní ọjọ́ yẹn.

Verse 13

يُنَبَّؤُا۟ ٱلْإِنسَـٰنُ يَوْمَئِذٍۭ بِمَا قَدَّمَ وَأَخَّرَ

Transliteration yunabba-u l-insānu yawma-idhin bimā qaddama wa-akhara

Yoruba Wọ́n máa fún ènìyàn ní ìró ní ọjọ́ yẹn nípa ohun tó tì síwájú (nínú iṣẹ́ rẹ̀) àti ohun tó fi kẹ́yìn (nínú orípa iṣẹ́ rẹ̀).

Verse 14

بَلِ ٱلْإِنسَـٰنُ عَلَىٰ نَفْسِهِۦ بَصِيرَةٌ

Transliteration bali l-insānu ʿalā nafsihi baṣīratun

Yoruba Ṣebí ènìyàn dá ara rẹ̀ mọ̀,

Verse 15

وَلَوْ أَلْقَىٰ مَعَاذِيرَهُۥ

Transliteration walaw alqā maʿādhīrahu

Yoruba ìbáà mú àwọn àwáwí rẹ̀ wá.

Verse 16

لَا تُحَرِّكْ بِهِۦ لِسَانَكَ لِتَعْجَلَ بِهِۦٓ

Transliteration lā tuḥarrik bihi lisānaka litaʿjala bihi

Yoruba Má ṣe gbé ahọ́n rẹ sí ìmísí láti kánjú ké e.

Verse 17

إِنَّ عَلَيْنَا جَمْعَهُۥ وَقُرْءَانَهُۥ

Transliteration inna ʿalaynā jamʿahu waqur'ānahu

Yoruba Dájúdájú Àwa l’A máa ṣe àkójọ rẹ̀ (sínú ọkàn rẹ) àti kíké rẹ̀.

Verse 18

فَإِذَا قَرَأْنَـٰهُ فَٱتَّبِعْ قُرْءَانَهُۥ

Transliteration fa-idhā qaranāhu fa-ittabiʿ qur'ānahu

Yoruba Nígbà tí A bá ń ké e (fún ọ), kí o sì máa tẹ̀lé kíké rẹ̀.

Verse 19

ثُمَّ إِنَّ عَلَيْنَا بَيَانَهُۥ

Transliteration thumma inna ʿalaynā bayānahu

Yoruba Lẹ́yìn náà, dájúdájú Àwa l’A máa ṣe àlàyé rẹ̀ fún ọ.

Verse 20

كَلَّا بَلْ تُحِبُّونَ ٱلْعَاجِلَةَ

Transliteration kallā bal tuḥibbūna l-ʿājilata

Yoruba Kò rí bẹ́ẹ̀, bí kò ṣe pé, ẹ nífẹ̀ẹ́ ayé ni.

Verse 21

وَتَذَرُونَ ٱلْـَٔاخِرَةَ

Transliteration watadharūna l-ākhirata

Yoruba Ẹ sì ń gbé ọ̀run jù sílẹ̀.

Verse 22

وُجُوهٌ يَوْمَئِذٍ نَّاضِرَةٌ

Transliteration wujūhun yawma-idhin nāḍiratun

Yoruba Àwọn ojú kan ní ọjọ́ yẹn yóò tutù (fún ìdùnnú).

Verse 23

إِلَىٰ رَبِّهَا نَاظِرَةٌ

Transliteration ilā rabbihā nāẓiratun

Yoruba Olúwa wọn ni wọn yóò máa wò.

Verse 24

وَوُجُوهٌ يَوْمَئِذٍۭ بَاسِرَةٌ

Transliteration wawujūhun yawma-idhin bāsiratun

Yoruba Àwọn ojú kan ní ọjọ́ yẹn sì máa bàjẹ́.

Verse 25

تَظُنُّ أَن يُفْعَلَ بِهَا فَاقِرَةٌ

Transliteration taẓunnu an yuf'ʿala bihā fāqiratun

Yoruba (Ojú náà) yóò mọ̀ dájú pé wọ́n máa fi aburú kan òhun.

Verse 26

كَلَّآ إِذَا بَلَغَتِ ٱلتَّرَاقِىَ

Transliteration kallā idhā balaghati l-tarāqiya

Yoruba Kò rí bẹ́ẹ̀, nígbà tí ẹ̀mí bá dé gògòńgò.

Verse 27

وَقِيلَ مَنْ ۜ رَاقٍ

Transliteration waqīla man rāqin

Yoruba A sì máa sọ pé: “Ǹjẹ́ olùpọfọ̀ kan wà bí (tí ó máa pọfọ̀ láti gbà á sílẹ̀ lọ́wọ́ ikú)?

Verse 28

وَظَنَّ أَنَّهُ ٱلْفِرَاقُ

Transliteration waẓanna annahu l-firāqu

Yoruba Ó sì máa dá a lójú pé dájúdájú ìpínyà ayé ti dé.

Verse 29

وَٱلْتَفَّتِ ٱلسَّاقُ بِٱلسَّاقِ

Transliteration wal-tafati l-sāqu bil-sāqi

Yoruba Ojúgun yó sì lọ́mọ́ ojúgun.

Verse 30

إِلَىٰ رَبِّكَ يَوْمَئِذٍ ٱلْمَسَاقُ

Transliteration ilā rabbika yawma-idhin l-masāqu

Yoruba Ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ sì ni wíwa ẹ̀dá lọ ní ọjọ́ yẹn.

Verse 31

فَلَا صَدَّقَ وَلَا صَلَّىٰ

Transliteration falā ṣaddaqa walā ṣallā

Yoruba Kò kúkú gba òdodo gbọ́, kò sì kírun.

Verse 32

وَلَـٰكِن كَذَّبَ وَتَوَلَّىٰ

Transliteration walākin kadhaba watawallā

Yoruba Ṣùgbọ́n ó pe òdodo ní irọ́. Ó sì kẹ̀yìn sí i.

Verse 33

ثُمَّ ذَهَبَ إِلَىٰٓ أَهْلِهِۦ يَتَمَطَّىٰٓ

Transliteration thumma dhahaba ilā ahlihi yatamaṭṭā

Yoruba Lẹ́yìn náà, ó lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn rẹ̀, ó sì ń ṣe fáàrí.

Verse 34

أَوْلَىٰ لَكَ فَأَوْلَىٰ

Transliteration awlā laka fa-awlā

Yoruba Ègbé ni fún ọ, ègbé ni sẹ́.

Verse 35

ثُمَّ أَوْلَىٰ لَكَ فَأَوْلَىٰٓ

Transliteration thumma awlā laka fa-awlā

Yoruba Lẹ́yìn náà, ègbé ni fún ọ, ègbé sì ni fún ọ sẹ́.

Verse 36

أَيَحْسَبُ ٱلْإِنسَـٰنُ أَن يُتْرَكَ سُدًى

Transliteration ayaḥsabu l-insānu an yut'raka sudan

Yoruba Ṣé ènìyàn lérò pé A máa fi òun sílẹ̀ lásán ni?

Verse 37

أَلَمْ يَكُ نُطْفَةً مِّن مَّنِىٍّ يُمْنَىٰ

Transliteration alam yaku nuṭ'fatan min maniyyin yum'nā

Yoruba Ṣé kò ti jẹ́ àtọ̀ mọnī tí wọ́n dà jáde sínú àpòlùkẹ́ ni?

Verse 38

ثُمَّ كَانَ عَلَقَةً فَخَلَقَ فَسَوَّىٰ

Transliteration thumma kāna ʿalaqatan fakhalaqa fasawwā

Yoruba Lẹ́yìn náà, ó di ẹ̀jẹ̀ dídì. (Allāhu) sì ṣẹ̀dá (rẹ̀). Ó sì ṣe é tó dọ́gba jálẹ̀ léèyàn.

Verse 39

فَجَعَلَ مِنْهُ ٱلزَّوْجَيْنِ ٱلذَّكَرَ وَٱلْأُنثَىٰٓ

Transliteration fajaʿala min'hu l-zawjayni l-dhakara wal-unthā

Yoruba (Allāhu) sì ṣe ìran méjì jáde láti ara rẹ̀, akọ àti abo.

Verse 40

أَلَيْسَ ذَٰلِكَ بِقَـٰدِرٍ عَلَىٰٓ أَن يُحْـِۧىَ ٱلْمَوْتَىٰ

Transliteration alaysa dhālika biqādirin ʿalā an yuḥ'yiya l-mawtā

Yoruba Ǹjẹ́ Ẹni tí Ó ṣe ìyẹn kò níí ní agbára láti jí àwọn òkú dìde bí?

Read Surah Al-Qiyamah in another language

All languages

All 114 surahs in Yoruba: the Qur’an in Yoruba.

Learn it in MyDugsi

Yoruba translation: Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni, from Quran.com. Transliteration: Quran.com. Recitation: Mishary Alafasy, from EveryAyah.com. MyDugsi is a learning aid, not a replacement for a qualified teacher.