MyDugsiStart learning

Surah Ya-Sin in Yoruba: translation and audio

Surah 36 · يس · Ya Sin · 83 verses

Surah Ya-Sin verse by verse: the Arabic with a recitation you can repeat, the transliteration, and the Yoruba translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni. For the meaning of every word, see Surah Ya-Sin word by word in English.

Verse 1

يسٓ

Transliteration ya-seen

Yoruba Yā sīn (Allāhu ló mọ ohun tí Ó gbàlérò pẹ̀lú àwọn háràfí náà.)1

Verse 2

وَٱلْقُرْءَانِ ٱلْحَكِيمِ

Transliteration wal-qur'āni l-ḥakīmi

Yoruba (Allāhu) fi Al-Ƙur’ān tí ó kún fún ọgbọ́n búra.1

Verse 3

إِنَّكَ لَمِنَ ٱلْمُرْسَلِينَ

Transliteration innaka lamina l-mur'salīna

Yoruba Dájúdájú ìwọ wà nínú àwọn Òjíṣẹ́.

Verse 4

عَلَىٰ صِرَٰطٍ مُّسْتَقِيمٍ

Transliteration ʿalā ṣirāṭin mus'taqīmin

Yoruba (O) wà lórí ọ̀nà tààrà (’Islām).

Verse 5

تَنزِيلَ ٱلْعَزِيزِ ٱلرَّحِيمِ

Transliteration tanzīla l-ʿazīzi l-raḥīmi

Yoruba (Al-Ƙur’ān jẹ́) ìmísí tó sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Alágbára, Àṣàkẹ́-ọ̀run

Verse 6

لِتُنذِرَ قَوْمًا مَّآ أُنذِرَ ءَابَآؤُهُمْ فَهُمْ غَـٰفِلُونَ

Transliteration litundhira qawman mā undhira ābāuhum fahum ghāfilūna

Yoruba nítorí kí o lè ṣèkìlọ̀ fún àwọn ènìyàn kan, (àwọn) tí wọn kò ṣe ìkìlọ̀ fún àwọn bàbá wọn rí. Nítorí náà, afọ́núfọ́ra sì ni wọ́n (nípa ìmọ̀nà).1

Verse 7

لَقَدْ حَقَّ ٱلْقَوْلُ عَلَىٰٓ أَكْثَرِهِمْ فَهُمْ لَا يُؤْمِنُونَ

Transliteration laqad ḥaqqa l-qawlu ʿalā aktharihim fahum lā yu'minūna

Yoruba Dájúdájú ọ̀rọ̀ náà ti kò lé ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn lórí; wọn kò sì níí gbàgbọ́.

Verse 8

إِنَّا جَعَلْنَا فِىٓ أَعْنَـٰقِهِمْ أَغْلَـٰلًا فَهِىَ إِلَى ٱلْأَذْقَانِ فَهُم مُّقْمَحُونَ

Transliteration innā jaʿalnā fī aʿnāqihim aghlālan fahiya ilā l-adhqāni fahum muq'maḥūna

Yoruba Dájúdájú Àwa ti kó ẹ̀wọ̀n sí wọn lọ́rùn (mọ́ ọwọ́ wọn). Ó sì ga dé àgbọ̀n (wọn). Wọ́n sì gà wọ́n lọ́rùn sókè.

Verse 9

وَجَعَلْنَا مِنۢ بَيْنِ أَيْدِيهِمْ سَدًّا وَمِنْ خَلْفِهِمْ سَدًّا فَأَغْشَيْنَـٰهُمْ فَهُمْ لَا يُبْصِرُونَ

Transliteration wajaʿalnā min bayni aydīhim saddan wamin khalfihim saddan fa-aghshaynāhum fahum lā yub'ṣirūna

Yoruba Àti pé Àwa fi gàgá kan síwájú wọn, gàgá kan sẹ́yìn wọn; A bò wọ́n lójú, wọn kò sì ríran.

Verse 10

وَسَوَآءٌ عَلَيْهِمْ ءَأَنذَرْتَهُمْ أَمْ لَمْ تُنذِرْهُمْ لَا يُؤْمِنُونَ

Transliteration wasawāon ʿalayhim a-andhartahum am lam tundhir'hum lā yu'minūna

Yoruba Bákan náà ni fún wọn, yálà o kìlọ̀ fún wọn tàbí o kò kìlọ̀ fún wọn; wọn kò níí gbàgbọ́.1

Verse 11

إِنَّمَا تُنذِرُ مَنِ ٱتَّبَعَ ٱلذِّكْرَ وَخَشِىَ ٱلرَّحْمَـٰنَ بِٱلْغَيْبِ ۖ فَبَشِّرْهُ بِمَغْفِرَةٍ وَأَجْرٍ كَرِيمٍ

Transliteration innamā tundhiru mani ittabaʿa l-dhik'ra wakhashiya l-raḥmāna bil-ghaybi fabashir'hu bimaghfiratin wa-ajrin karīmin

Yoruba Ẹni tí ìkìlọ̀ rẹ (máa wúlò fún) ni ẹni tí ó tẹ̀lé Ìrántí (al-Ƙur’ān), tí ó sì páyà Àjọkẹ́-ayé ní ìkọ̀kọ̀. Nítorí náà, fún un ní ìró ìdùnnú nípa àforíjìn àti ẹ̀san alápọ̀n-ọ́nlé.

Verse 12

إِنَّا نَحْنُ نُحْىِ ٱلْمَوْتَىٰ وَنَكْتُبُ مَا قَدَّمُوا۟ وَءَاثَـٰرَهُمْ ۚ وَكُلَّ شَىْءٍ أَحْصَيْنَـٰهُ فِىٓ إِمَامٍ مُّبِينٍ

Transliteration innā naḥnu nuḥ'yī l-mawtā wanaktubu mā qaddamū waāthārahum wakulla shayin aḥṣaynāhu fī imāmin mubīnin

Yoruba Dájúdájú Àwa, Àwa l’À ń sọ àwọn òkú di alàyè. A sì ń ṣe àkọsílẹ̀ ohun tí wọ́n tì síwájú àti orípa (iṣẹ́ ọwọ́) wọn. Gbogbo n̄ǹkan ni A ṣe àkọsílẹ̀ rẹ̀ sínú tírà kan tó yanjú.

Verse 13

وَٱضْرِبْ لَهُم مَّثَلًا أَصْحَـٰبَ ٱلْقَرْيَةِ إِذْ جَآءَهَا ٱلْمُرْسَلُونَ

Transliteration wa-iḍ'rib lahum mathalan aṣḥāba l-qaryati idh jāahā l-mur'salūna

Yoruba Fi àpèjúwe kan lélẹ̀ fún wọn nípa àwọn ará ìlú kan nígbà tí àwọn Òjíṣẹ́ wá bá wọn.

Verse 14

إِذْ أَرْسَلْنَآ إِلَيْهِمُ ٱثْنَيْنِ فَكَذَّبُوهُمَا فَعَزَّزْنَا بِثَالِثٍ فَقَالُوٓا۟ إِنَّآ إِلَيْكُم مُّرْسَلُونَ

Transliteration idh arsalnā ilayhimu ith'nayni fakadhabūhumā faʿazzaznā bithālithin faqālū innā ilaykum mur'salūna

Yoruba (Rántí) nígbà tí A rán Òjíṣẹ́ méjì níṣẹ́ sí wọn. Wọ́n pe àwọn méjèèjì ní òpùrọ́. A sì fi ẹnì kẹta ró àwọn méjèèjì lágbára. Wọ́n sì sọ pé: “Dájúdájú àwa ni Òjíṣẹ́ tí Wọ́n rán níṣẹ́ si yín.”1

Verse 15

قَالُوا۟ مَآ أَنتُمْ إِلَّا بَشَرٌ مِّثْلُنَا وَمَآ أَنزَلَ ٱلرَّحْمَـٰنُ مِن شَىْءٍ إِنْ أَنتُمْ إِلَّا تَكْذِبُونَ

Transliteration qālū mā antum illā basharun mith'lunā wamā anzala l-raḥmānu min shayin in antum illā takdhibūna

Yoruba Wọ́n wí pé: “Ẹ̀yin kò jẹ́ kiní kan bí kò ṣe abara bí irú tiwa. Àjọkẹ́-ayé kò sì sọ n̄ǹkan kan kalẹ̀. Ẹ̀yin kò sì jẹ́ kiní kan bí kò ṣe òpùrọ́.”

Verse 16

قَالُوا۟ رَبُّنَا يَعْلَمُ إِنَّآ إِلَيْكُمْ لَمُرْسَلُونَ

Transliteration qālū rabbunā yaʿlamu innā ilaykum lamur'salūna

Yoruba Wọ́n sọ pé: “Olúwa wa mọ̀ pé dájúdájú àwa ni Òjíṣẹ́ tí Wọ́n rán níṣẹ́ si yín.

Verse 17

وَمَا عَلَيْنَآ إِلَّا ٱلْبَلَـٰغُ ٱلْمُبِينُ

Transliteration wamā ʿalaynā illā l-balāghu l-mubīnu

Yoruba Kò sì sí ojúṣe kan fún wa bí kò ṣe ìkéde (ẹ̀sìn) tó yanjú.”

Verse 18

قَالُوٓا۟ إِنَّا تَطَيَّرْنَا بِكُمْ ۖ لَئِن لَّمْ تَنتَهُوا۟ لَنَرْجُمَنَّكُمْ وَلَيَمَسَّنَّكُم مِّنَّا عَذَابٌ أَلِيمٌ

Transliteration qālū innā taṭayyarnā bikum la-in lam tantahū lanarjumannakum walayamassannakum minnā ʿadhābun alīmun

Yoruba Wọ́n wí pé: “Dájúdájú àwa rí àmì aburú lára yín. Tí ẹ kò bá jáwọ́ (níbi ìpèpè yín), dájúdájú a máa sọ yín lókò pa. Ìyà ẹlẹ́ta-eléro yó sì jẹ yín láti ọ̀dọ̀ wa.”

Verse 19

قَالُوا۟ طَـٰٓئِرُكُم مَّعَكُمْ ۚ أَئِن ذُكِّرْتُم ۚ بَلْ أَنتُمْ قَوْمٌ مُّسْرِفُونَ

Transliteration qālū ṭāirukum maʿakum a-in dhukkir'tum bal antum qawmun mus'rifūna

Yoruba Wọ́n sọ pé: “Àmì aburú yín ń bẹ pẹ̀lú yín. Ṣé nítorí pé wọ́n ṣe ìṣítí fún yín (l’ẹ fi rí àmì aburú lára wa)? Kò rí bẹ́ẹ̀! Ìjọ alákọyọ ni yín ni.”

Verse 20

وَجَآءَ مِنْ أَقْصَا ٱلْمَدِينَةِ رَجُلٌ يَسْعَىٰ قَالَ يَـٰقَوْمِ ٱتَّبِعُوا۟ ٱلْمُرْسَلِينَ

Transliteration wajāa min aqṣā l-madīnati rajulun yasʿā qāla yāqawmi ittabiʿū l-mur'salīna

Yoruba Ọkùnrin kan sáré dé láti òpin ìlú náà, ó wí pé: “Ẹ̀yin ènìyàn mi, ẹ tẹ̀lé àwọn Òjíṣẹ́ náà.

Verse 21

ٱتَّبِعُوا۟ مَن لَّا يَسْـَٔلُكُمْ أَجْرًا وَهُم مُّهْتَدُونَ

Transliteration ittabiʿū man lā yasalukum ajran wahum muh'tadūna

Yoruba Ẹ tẹ̀lé ẹni tí kò bèèrè owó-ọ̀yà kan ní ọwọ́ yín. Olùmọ̀nà sì ni wọ́n.

Verse 22

وَمَا لِىَ لَآ أَعْبُدُ ٱلَّذِى فَطَرَنِى وَإِلَيْهِ تُرْجَعُونَ

Transliteration wamā liya lā aʿbudu alladhī faṭaranī wa-ilayhi tur'jaʿūna

Yoruba Kí ni ó máa mú mi tí èmi kò fi níí jọ́sìn fún Ẹni tí Ó pilẹ̀ ẹ̀dá mi? Ọ̀dọ̀ Rẹ̀ sì ni wọn yóò da yín padà sí.

Verse 23

ءَأَتَّخِذُ مِن دُونِهِۦٓ ءَالِهَةً إِن يُرِدْنِ ٱلرَّحْمَـٰنُ بِضُرٍّ لَّا تُغْنِ عَنِّى شَفَـٰعَتُهُمْ شَيْـًٔا وَلَا يُنقِذُونِ

Transliteration a-attakhidhu min dūnihi ālihatan in yurid'ni l-raḥmānu biḍurrin lā tugh'ni ʿannī shafāʿatuhum shayan walā yunqidhūni

Yoruba Ṣé kí èmi sọ àwọn kan di ọlọ́hun lẹ́yìn Allāhu ni? Tí Àjọkẹ́-ayé bá fẹ́ fi ìnira kàn mí, ìṣìpẹ̀ wọn kò lè rọ̀ mí lọ́rọ̀ kiní kan, wọn kò sì lè gbà mí là.

Verse 24

إِنِّىٓ إِذًا لَّفِى ضَلَـٰلٍ مُّبِينٍ

Transliteration innī idhan lafī ḍalālin mubīnin

Yoruba (Bí èmi kò bá jọ́sìn fún Allāhu) nígbà náà dájúdájú mo ti wà nínú ìṣìnà pọ́nńbélé.

Verse 25

إِنِّىٓ ءَامَنتُ بِرَبِّكُمْ فَٱسْمَعُونِ

Transliteration innī āmantu birabbikum fa-is'maʿūni

Yoruba Dájúdájú èmi gbàgbọ́ nínú Olúwa Ẹlẹ́dàá yín. Nítorí náà, ẹ gbọ́ mi.” (Àwọn aláìgbàgbọ́ sì pa onígbàgbọ́ òdodo yìí.)

Verse 26

قِيلَ ٱدْخُلِ ٱلْجَنَّةَ ۖ قَالَ يَـٰلَيْتَ قَوْمِى يَعْلَمُونَ

Transliteration qīla ud'khuli l-janata qāla yālayta qawmī yaʿlamūna

Yoruba (Àwọn mọlāika) wọ́n sọ pé: “Wọ inú Ọgbà Ìdẹ̀ra.” Ó sọ pé: “Àwọn ènìyàn mi ìbá ní ìmọ̀

Verse 27

بِمَا غَفَرَ لِى رَبِّى وَجَعَلَنِى مِنَ ٱلْمُكْرَمِينَ

Transliteration bimā ghafara lī rabbī wajaʿalanī mina l-muk'ramīna

Yoruba nípa bí Olúwa mi ṣe foríjìn mí àti (bí) Ó ṣe fi mí sí ara àwọn alápọ̀n-ọ́nlé (wọn ìbá ronú pìwàdà).”

Verse 28

۞ وَمَآ أَنزَلْنَا عَلَىٰ قَوْمِهِۦ مِنۢ بَعْدِهِۦ مِن جُندٍ مِّنَ ٱلسَّمَآءِ وَمَا كُنَّا مُنزِلِينَ

Transliteration wamā anzalnā ʿalā qawmihi min baʿdihi min jundin mina l-samāi wamā kunnā munzilīna

Yoruba A kò sọ ọmọ ogun kan kalẹ̀ lé àwọn ènìyàn rẹ̀ lórí láti sánmọ̀ lẹ́yìn rẹ̀. A kò sì sọ (mọlāika kan) kalẹ̀ (fún ìparun wọn).

Verse 29

إِن كَانَتْ إِلَّا صَيْحَةً وَٰحِدَةً فَإِذَا هُمْ خَـٰمِدُونَ

Transliteration in kānat illā ṣayḥatan wāḥidatan fa-idhā hum khāmidūna

Yoruba (Ìparun wọn) kò jẹ́ kiní kan bí kò ṣe igbe ẹyọ kan; nígbà náà ni wọ́n di òkú kalẹ̀.

Verse 30

يَـٰحَسْرَةً عَلَى ٱلْعِبَادِ ۚ مَا يَأْتِيهِم مِّن رَّسُولٍ إِلَّا كَانُوا۟ بِهِۦ يَسْتَهْزِءُونَ

Transliteration yāḥasratan ʿalā l-ʿibādi mā yatīhim min rasūlin illā kānū bihi yastahziūna

Yoruba Àbámọ̀ mà ni fún àwọn ẹrúsìn náà (nígbà tí wọ́n bá fojú ara wọn rí Iná); òjíṣẹ́ kan kò níí wá bá wọn àyàfi kí wọ́n máa fi ṣe yẹ̀yẹ́.

Verse 31

أَلَمْ يَرَوْا۟ كَمْ أَهْلَكْنَا قَبْلَهُم مِّنَ ٱلْقُرُونِ أَنَّهُمْ إِلَيْهِمْ لَا يَرْجِعُونَ

Transliteration alam yaraw kam ahlaknā qablahum mina l-qurūni annahum ilayhim lā yarjiʿūna

Yoruba Ṣé wọn kò wòye pé mélòó mélòó nínú àwọn ìran tí A ti parẹ́ ṣíwájú wọn? (Ṣé wọn kò wòye pé) dájúdájú wọn kò padà sí ọ̀dọ̀ wọn mọ́ (nílé ayé) ni?

Verse 32

وَإِن كُلٌّ لَّمَّا جَمِيعٌ لَّدَيْنَا مُحْضَرُونَ

Transliteration wa-in kullun lammā jamīʿun ladaynā muḥ'ḍarūna

Yoruba Dájúdájú gbogbo wọn pátápátá sì ni (àwọn mọlāika) máa kó wá sí ọ̀dọ̀ Wa.

Verse 33

وَءَايَةٌ لَّهُمُ ٱلْأَرْضُ ٱلْمَيْتَةُ أَحْيَيْنَـٰهَا وَأَخْرَجْنَا مِنْهَا حَبًّا فَمِنْهُ يَأْكُلُونَ

Transliteration waāyatun lahumu l-arḍu l-maytatu aḥyaynāhā wa-akhrajnā min'hā ḥabban famin'hu yakulūna

Yoruba Àmì ni òkú ilẹ̀jẹ́ fún wọn. A sọ ọ́ di ààyè. A sì mú èso jáde láti inú rẹ̀. Wọ́n sì ń jẹ nínú rẹ̀.

Verse 34

وَجَعَلْنَا فِيهَا جَنَّـٰتٍ مِّن نَّخِيلٍ وَأَعْنَـٰبٍ وَفَجَّرْنَا فِيهَا مِنَ ٱلْعُيُونِ

Transliteration wajaʿalnā fīhā jannātin min nakhīlin wa-aʿnābin wafajjarnā fīhā mina l-ʿuyūni

Yoruba A tún ṣe àwọn ọgbà dàbínù àti àjàrà sórí ilẹ̀. A sì mú àwọn odò ìṣẹ́lẹ̀rú ṣàn láti inú rẹ̀

Verse 35

لِيَأْكُلُوا۟ مِن ثَمَرِهِۦ وَمَا عَمِلَتْهُ أَيْدِيهِمْ ۖ أَفَلَا يَشْكُرُونَ

Transliteration liyakulū min thamarihi wamā ʿamilathu aydīhim afalā yashkurūna

Yoruba nítorí kí wọ́n lè jẹ nínú èso rẹ̀ àti èyí tí wọ́n fi ọwọ́ ara wọn ṣe!Ṣé wọn kò níí dúpẹ́ ni?

Verse 36

سُبْحَـٰنَ ٱلَّذِى خَلَقَ ٱلْأَزْوَٰجَ كُلَّهَا مِمَّا تُنۢبِتُ ٱلْأَرْضُ وَمِنْ أَنفُسِهِمْ وَمِمَّا لَا يَعْلَمُونَ

Transliteration sub'ḥāna alladhī khalaqa l-azwāja kullahā mimmā tunbitu l-arḍu wamin anfusihim wamimmā lā yaʿlamūna

Yoruba Mímọ́ ni fún Ẹni tí Ó ṣẹ̀dá gbogbo n̄ǹkan ní oríṣiríṣi nínú ohun tí ilẹ̀ ń hù jáde àti nínú ẹ̀mí ara wọn àti nínú ohun tí wọn kò mọ̀.1

Verse 37

وَءَايَةٌ لَّهُمُ ٱلَّيْلُ نَسْلَخُ مِنْهُ ٱلنَّهَارَ فَإِذَا هُم مُّظْلِمُونَ

Transliteration waāyatun lahumu al-laylu naslakhu min'hu l-nahāra fa-idhā hum muẓ'limūna

Yoruba Àmì kan ni òru jẹ́ fún wọn, tí À ń yọ ọ̀sán jáde láti inú rẹ̀. Nígbà náà (tí A bá yọ ọ́ tán) wọn yóò tún wà nínú òkùnkùn (alẹ́ mìíràn).1

Verse 38

وَٱلشَّمْسُ تَجْرِى لِمُسْتَقَرٍّ لَّهَا ۚ ذَٰلِكَ تَقْدِيرُ ٱلْعَزِيزِ ٱلْعَلِيمِ

Transliteration wal-shamsu tajrī limus'taqarrin lahā dhālika taqdīru l-ʿazīzi l-ʿalīmi

Yoruba Àti pé òòrùn yóò máa rìn lọ sí àyè rẹ̀. Ìyẹn ni ètò (ti) Alágbára, Onímọ̀.

Verse 39

وَٱلْقَمَرَ قَدَّرْنَـٰهُ مَنَازِلَ حَتَّىٰ عَادَ كَٱلْعُرْجُونِ ٱلْقَدِيمِ

Transliteration wal-qamara qaddarnāhu manāzila ḥattā ʿāda kal-ʿur'jūni l-qadīmi

Yoruba Òṣùpá náà, A ti ṣe òdíwọ̀n àwọn ibùsọ̀ fún un (tí ó ti ma máa tóbi sí i) títí ó máa fi padà dà bíi àran ọ̀pẹ tó ti pẹ́ (gbígbẹ).

Verse 40

لَا ٱلشَّمْسُ يَنۢبَغِى لَهَآ أَن تُدْرِكَ ٱلْقَمَرَ وَلَا ٱلَّيْلُ سَابِقُ ٱلنَّهَارِ ۚ وَكُلٌّ فِى فَلَكٍ يَسْبَحُونَ

Transliteration lā l-shamsu yanbaghī lahā an tud'rika l-qamara walā al-laylu sābiqu l-nahāri wakullun fī falakin yasbaḥūna

Yoruba Kò yẹ fún òòrùn láti lo àsìkò òṣùpá. Kò sì yẹ fún alẹ́ láti lo àsìkò ọ̀sán. Ìkọ̀ọ̀kan wà ní òpópónà róbótó tó ń tọ̀.

Verse 41

وَءَايَةٌ لَّهُمْ أَنَّا حَمَلْنَا ذُرِّيَّتَهُمْ فِى ٱلْفُلْكِ ٱلْمَشْحُونِ

Transliteration waāyatun lahum annā ḥamalnā dhurriyyatahum fī l-ful'ki l-mashḥūni

Yoruba Àmì kan tún ni fún wọn pé, dájúdájú Àwa gbé àwọn àrọ́mọdọ́mọ wọn gun ọkọ̀ ojú-omi tó kún kẹ́kẹ́.

Verse 42

وَخَلَقْنَا لَهُم مِّن مِّثْلِهِۦ مَا يَرْكَبُونَ

Transliteration wakhalaqnā lahum min mith'lihi mā yarkabūna

Yoruba A tún ṣẹ̀dá (òmíràn) fún wọn nínú irú rẹ̀ tí wọn yóò máa gún.1

Verse 43

وَإِن نَّشَأْ نُغْرِقْهُمْ فَلَا صَرِيخَ لَهُمْ وَلَا هُمْ يُنقَذُونَ

Transliteration wa-in nasha nugh'riq'hum falā ṣarīkha lahum walā hum yunqadhūna

Yoruba Tí A bá fẹ́ Àwa ìbá tẹ̀ wọ́n rì sínú omi. Kò níí sí olùrànlọ́wọ́ kan fún wọn. Wọn kò sì níí gbà wọ́n là.

Verse 44

إِلَّا رَحْمَةً مِّنَّا وَمَتَـٰعًا إِلَىٰ حِينٍ

Transliteration illā raḥmatan minnā wamatāʿan ilā ḥīnin

Yoruba Àfi (kí Á fi) ìkẹ́ kan láti ọ̀dọ̀ Wa (yọ wọ́n jáde, kí A sì tún fún wọn ní) ìgbádùn ayé títí di ìgbà díẹ̀.

Verse 45

وَإِذَا قِيلَ لَهُمُ ٱتَّقُوا۟ مَا بَيْنَ أَيْدِيكُمْ وَمَا خَلْفَكُمْ لَعَلَّكُمْ تُرْحَمُونَ

Transliteration wa-idhā qīla lahumu ittaqū mā bayna aydīkum wamā khalfakum laʿallakum tur'ḥamūna

Yoruba (Wọ́n máa gbúnrí) nígbà tí A bá sọ fún wọn pé: “Ẹ ṣọ́ra fún ohun tó wà níwájú yínàti ohun tó wà lẹ́yìn yín2 nítorí kí A lè kẹ yín.”

Verse 46

وَمَا تَأْتِيهِم مِّنْ ءَايَةٍ مِّنْ ءَايَـٰتِ رَبِّهِمْ إِلَّا كَانُوا۟ عَنْهَا مُعْرِضِينَ

Transliteration wamā tatīhim min āyatin min āyāti rabbihim illā kānū ʿanhā muʿ'riḍīna

Yoruba Àti pé āyah kan nínú àwọn āyah Olúwa wọn kò níí wá bá wọn àfi kí wọ́n máa gbúnrí kúrò níbẹ̀.

Verse 47

وَإِذَا قِيلَ لَهُمْ أَنفِقُوا۟ مِمَّا رَزَقَكُمُ ٱللَّهُ قَالَ ٱلَّذِينَ كَفَرُوا۟ لِلَّذِينَ ءَامَنُوٓا۟ أَنُطْعِمُ مَن لَّوْ يَشَآءُ ٱللَّهُ أَطْعَمَهُۥٓ إِنْ أَنتُمْ إِلَّا فِى ضَلَـٰلٍ مُّبِينٍ

Transliteration wa-idhā qīla lahum anfiqū mimmā razaqakumu l-lahu qāla alladhīna kafarū lilladhīna āmanū anuṭ'ʿimu man law yashāu l-lahu aṭʿamahu in antum illā fī ḍalālin mubīnin

Yoruba Nígbà tí A bá sì sọ fún wọn pé: “Ẹ ná nínú ohun tí Allāhu ṣe ní arísìkí fún yín.”, àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ yóò wí fún àwọn tó gbàgbọ́ pé: “Ṣé kí á bọ́ ẹni tí (ó jẹ́ pé) Allāhu ìbá fẹ́ ìbá bọ́ ọ (àmọ́ kò bọ́ ọ. Àwa náà kò sì níí bá A bọ́ ọ)?” Kí ni ẹ̀yin bí kò ṣe pé (ẹ wà) nínú ìṣìnà pọ́nńbélé.

Verse 48

وَيَقُولُونَ مَتَىٰ هَـٰذَا ٱلْوَعْدُ إِن كُنتُمْ صَـٰدِقِينَ

Transliteration wayaqūlūna matā hādhā l-waʿdu in kuntum ṣādiqīna

Yoruba Wọ́n ń wí pé: “Ìgbà wo ni àdéhùn yìí yóò ṣẹ tí ẹ bá jẹ́ olódodo?”

Verse 49

مَا يَنظُرُونَ إِلَّا صَيْحَةً وَٰحِدَةً تَأْخُذُهُمْ وَهُمْ يَخِصِّمُونَ

Transliteration mā yanẓurūna illā ṣayḥatan wāḥidatan takhudhuhum wahum yakhiṣṣimūna

Yoruba Wọn kò retí kiní kan bí kò ṣe igbe ẹyọ kan ṣoṣo tí ó máa gbá wọn mú nígbà tí wọ́n bá ń ṣe àríyànjiyàn lọ́wọ́.

Verse 50

فَلَا يَسْتَطِيعُونَ تَوْصِيَةً وَلَآ إِلَىٰٓ أَهْلِهِمْ يَرْجِعُونَ

Transliteration falā yastaṭīʿūna tawṣiyatan walā ilā ahlihim yarjiʿūna

Yoruba Nígbà náà, wọn kò níí lè sọ àsọọ́lẹ̀ kan. Wọn kò sì níí lè padà sí ọ̀dọ̀ ará ilé wọn.

Verse 51

وَنُفِخَ فِى ٱلصُّورِ فَإِذَا هُم مِّنَ ٱلْأَجْدَاثِ إِلَىٰ رَبِّهِمْ يَنسِلُونَ

Transliteration wanufikha fī l-ṣūri fa-idhā hum mina l-ajdāthi ilā rabbihim yansilūna

Yoruba Wọ́n á sì fọn fèrè oníwo fún àjíǹde, nígbà náà ni wọn yóò máa sáré jáde láti inú sàréè wá sí ọ̀dọ̀ Olúwa wọn.

Verse 52

قَالُوا۟ يَـٰوَيْلَنَا مَنۢ بَعَثَنَا مِن مَّرْقَدِنَا ۜ ۗ هَـٰذَا مَا وَعَدَ ٱلرَّحْمَـٰنُ وَصَدَقَ ٱلْمُرْسَلُونَ

Transliteration qālū yāwaylanā man baʿathanā min marqadinā hādhā mā waʿada l-raḥmānu waṣadaqa l-mur'salūna

Yoruba Wọ́n á wí pé: “Ègbé wa ò! Ta ni ó ta wá jí láti ojú oorun wa?” Èyí ni n̄ǹkan tí Àjọkẹ́-ayé ṣe ní àdéhùn. Àwọn Òjíṣẹ́ sì ti sọ òdodo (nípa rẹ̀).

Verse 53

إِن كَانَتْ إِلَّا صَيْحَةً وَٰحِدَةً فَإِذَا هُمْ جَمِيعٌ لَّدَيْنَا مُحْضَرُونَ

Transliteration in kānat illā ṣayḥatan wāḥidatan fa-idhā hum jamīʿun ladaynā muḥ'ḍarūna

Yoruba Kò jẹ́ kiní kan tayọ igbe ẹyọ kan ṣoṣo. Nígbà náà ni (àwọn mọlāika) yóò kó gbogbo wọn wá sí ọ̀dọ̀ Wa.

Verse 54

فَٱلْيَوْمَ لَا تُظْلَمُ نَفْسٌ شَيْـًٔا وَلَا تُجْزَوْنَ إِلَّا مَا كُنتُمْ تَعْمَلُونَ

Transliteration fal-yawma lā tuẓ'lamu nafsun shayan walā tuj'zawna illā mā kuntum taʿmalūna

Yoruba Nítorí náà, ní òní wọn kò níí ṣe àbòsí kiní kan fún ẹ̀mí kan. A kò sì níí san yín ní ẹ̀san àfi ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.

Verse 55

إِنَّ أَصْحَـٰبَ ٱلْجَنَّةِ ٱلْيَوْمَ فِى شُغُلٍ فَـٰكِهُونَ

Transliteration inna aṣḥāba l-janati l-yawma fī shughulin fākihūna

Yoruba Dájúdájú ní òní, àwọn èrò inú Ọgbà Ìdẹ̀ra yóò kún fún ìgbádùn.

Verse 56

هُمْ وَأَزْوَٰجُهُمْ فِى ظِلَـٰلٍ عَلَى ٱلْأَرَآئِكِ مُتَّكِـُٔونَ

Transliteration hum wa-azwājuhum fī ẓilālin ʿalā l-arāiki muttakiūna

Yoruba Àwọn àti àwọn ìyàwó wọn yóò wà lábẹ́ àwọn ibòji, wọn yó sì rọ̀gbọ̀kú sórí àwọn ibùsùn.

Verse 57

لَهُمْ فِيهَا فَـٰكِهَةٌ وَلَهُم مَّا يَدَّعُونَ

Transliteration lahum fīhā fākihatun walahum mā yaddaʿūna

Yoruba Èso wà nínú rẹ̀ fún wọn. Ohun tí wọ́n yóò máa bèèrè fún tún wà fún wọn pẹ̀lú.

Verse 58

سَلَـٰمٌ قَوْلًا مِّن رَّبٍّ رَّحِيمٍ

Transliteration salāmun qawlan min rabbin raḥīmin

Yoruba Àlàáfíà ni ọ̀rọ̀ tí ó má máa wá láti ọ̀dọ̀ Olúwa, Àṣàkẹ́-ọ̀run.

Verse 59

وَٱمْتَـٰزُوا۟ ٱلْيَوْمَ أَيُّهَا ٱلْمُجْرِمُونَ

Transliteration wa-im'tāzū l-yawma ayyuhā l-muj'rimūna

Yoruba Ẹ̀yin ẹlẹ́ṣẹ̀, ẹ bọ́ sí ọ̀tọ̀ ní òní.

Verse 60

۞ أَلَمْ أَعْهَدْ إِلَيْكُمْ يَـٰبَنِىٓ ءَادَمَ أَن لَّا تَعْبُدُوا۟ ٱلشَّيْطَـٰنَ ۖ إِنَّهُۥ لَكُمْ عَدُوٌّ مُّبِينٌ

Transliteration alam aʿhad ilaykum yābanī ādama an lā taʿbudū l-shayṭāna innahu lakum ʿaduwwun mubīnun

Yoruba Ẹ̀yin ọmọ (Ànábì) Ādam, ṣe Èmi kò ti pa yín ní àṣẹ pé, ẹ kò gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún Èṣù? Dájúdájú òun ni ọ̀tá pọ́nńbélé fún yín.

Verse 61

وَأَنِ ٱعْبُدُونِى ۚ هَـٰذَا صِرَٰطٌ مُّسْتَقِيمٌ

Transliteration wa-ani uʿ'budūnī hādhā ṣirāṭun mus'taqīmun

Yoruba Àti pé kí ẹ jọ́sìn fún Mi. Èyí ni ọ̀nà tààrà.

Verse 62

وَلَقَدْ أَضَلَّ مِنكُمْ جِبِلًّا كَثِيرًا ۖ أَفَلَمْ تَكُونُوا۟ تَعْقِلُونَ

Transliteration walaqad aḍalla minkum jibillan kathīran afalam takūnū taʿqilūna

Yoruba Àti pé (Èṣù) kúkú ti ṣi ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ẹ̀dá lọ́nà nínú yín. Ṣé ẹ kò níí ṣe làákàyè ni?

Verse 63

هَـٰذِهِۦ جَهَنَّمُ ٱلَّتِى كُنتُمْ تُوعَدُونَ

Transliteration hādhihi jahannamu allatī kuntum tūʿadūna

Yoruba Èyí ni iná Jahanamọ tí À ń ṣe ní àdéhùn fún yín.

Verse 64

ٱصْلَوْهَا ٱلْيَوْمَ بِمَا كُنتُمْ تَكْفُرُونَ

Transliteration iṣ'lawhā l-yawma bimā kuntum takfurūna

Yoruba Ẹ wọ inú rẹ̀ ní òní nítorí pé, ẹ̀yin jẹ́ aláìgbàgbọ́.

Verse 65

ٱلْيَوْمَ نَخْتِمُ عَلَىٰٓ أَفْوَٰهِهِمْ وَتُكَلِّمُنَآ أَيْدِيهِمْ وَتَشْهَدُ أَرْجُلُهُم بِمَا كَانُوا۟ يَكْسِبُونَ

Transliteration al-yawma nakhtimu ʿalā afwāhihim watukallimunā aydīhim watashhadu arjuluhum bimā kānū yaksibūna

Yoruba Ní òní, A máa di ẹnu wọn pa. Àwọn ọwọ́ wọn yó sì máa bá Wa sọ̀rọ̀. Àwọn ẹsẹ̀ wọn yó sì máa jẹ́rìí sí ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́.

Verse 66

وَلَوْ نَشَآءُ لَطَمَسْنَا عَلَىٰٓ أَعْيُنِهِمْ فَٱسْتَبَقُوا۟ ٱلصِّرَٰطَ فَأَنَّىٰ يُبْصِرُونَ

Transliteration walaw nashāu laṭamasnā ʿalā aʿyunihim fa-is'tabaqū l-ṣirāṭa fa-annā yub'ṣirūna

Yoruba Tí ó bá jẹ́ pé A bá fẹ́, Àwa ìbá fọ́ wọn lójú, wọn ìbá sì yára wá si ojú ọ̀nà, báwo ni wọ́n ṣe máa ríran ná?

Verse 67

وَلَوْ نَشَآءُ لَمَسَخْنَـٰهُمْ عَلَىٰ مَكَانَتِهِمْ فَمَا ٱسْتَطَـٰعُوا۟ مُضِيًّا وَلَا يَرْجِعُونَ

Transliteration walaw nashāu lamasakhnāhum ʿalā makānatihim famā is'taṭāʿū muḍiyyan walā yarjiʿūna

Yoruba Tí ó bá jẹ́ pé A bá fẹ́, Àwa ìbá yí wọn padà sí ẹ̀dá mìíràn nínú ibùgbé wọn. Wọn kò sì níí lágbára láti lọ síwájú. Wọn kò sì níí padà sẹ́yìn.

Verse 68

وَمَن نُّعَمِّرْهُ نُنَكِّسْهُ فِى ٱلْخَلْقِ ۖ أَفَلَا يَعْقِلُونَ

Transliteration waman nuʿammir'hu nunakkis'hu fī l-khalqi afalā yaʿqilūna

Yoruba Ẹnikẹ́ni tí A bá fún ní ẹ̀mí gígùn lò, A óò sọ ẹ̀dá rẹ̀ di ọ̀lẹ, ṣé wọn kò níí ṣe làákàyè ni!

Verse 69

وَمَا عَلَّمْنَـٰهُ ٱلشِّعْرَ وَمَا يَنۢبَغِى لَهُۥٓ ۚ إِنْ هُوَ إِلَّا ذِكْرٌ وَقُرْءَانٌ مُّبِينٌ

Transliteration wamā ʿallamnāhu l-shiʿ'ra wamā yanbaghī lahu in huwa illā dhik'run waqur'ānun mubīnun

Yoruba A kò kọ́ Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - ní ewì. Kò yẹ ẹ́ (kò sì rọ̀ ọ́ lọ́rùn láti kéwì). Kí ni ohun (tí A fi ránṣẹ́ sí i) bí kò ṣe ìrántí àti al-Ƙur’ān pọ́nńbélé

Verse 70

لِّيُنذِرَ مَن كَانَ حَيًّا وَيَحِقَّ ٱلْقَوْلُ عَلَى ٱلْكَـٰفِرِينَ

Transliteration liyundhira man kāna ḥayyan wayaḥiqqa l-qawlu ʿalā l-kāfirīna

Yoruba nítorí kí ó lè ṣèkìlọ̀ fún ẹni tí ó jẹ́ alààyè àti nítorí kí ọ̀rọ̀ náà lè kò lórí àwọn aláìgbàgbọ́.

Verse 71

أَوَلَمْ يَرَوْا۟ أَنَّا خَلَقْنَا لَهُم مِّمَّا عَمِلَتْ أَيْدِينَآ أَنْعَـٰمًا فَهُمْ لَهَا مَـٰلِكُونَ

Transliteration awalam yaraw annā khalaqnā lahum mimmā ʿamilat aydīnā anʿāman fahum lahā mālikūna

Yoruba Ṣé wọn kò wòye pé dájúdájú Àwa l’A ṣẹ̀dá nínú ohun tí A fi ọwọ́ Wa ṣe (tí ó jẹ́) àwọn ẹran-ọ̀sìn fún wọn? Wọ́n sì ní ìkápá lórí wọn.

Verse 72

وَذَلَّلْنَـٰهَا لَهُمْ فَمِنْهَا رَكُوبُهُمْ وَمِنْهَا يَأْكُلُونَ

Transliteration wadhallalnāhā lahum famin'hā rakūbuhum wamin'hā yakulūna

Yoruba A tẹ̀ wọ́n lórí ba fún wọn; wọ́n ń gùn nínú wọn, wọ́n sì ń jẹ nínú wọn.

Verse 73

وَلَهُمْ فِيهَا مَنَـٰفِعُ وَمَشَارِبُ ۖ أَفَلَا يَشْكُرُونَ

Transliteration walahum fīhā manāfiʿu wamashāribu afalā yashkurūna

Yoruba Àwọn àǹfààní àti ohun mímu tún wà fún wọn nínú rẹ̀. Ṣé wọn kò níí dúpẹ́ ni?

Verse 74

وَٱتَّخَذُوا۟ مِن دُونِ ٱللَّهِ ءَالِهَةً لَّعَلَّهُمْ يُنصَرُونَ

Transliteration wa-ittakhadhū min dūni l-lahi ālihatan laʿallahum yunṣarūna

Yoruba Wọ́n sọ àwọn kan di ọlọ́hun lẹ́yìn Allāhu nítorí kí wọ́n lè ṣàrànṣe fún wọn!

Verse 75

لَا يَسْتَطِيعُونَ نَصْرَهُمْ وَهُمْ لَهُمْ جُندٌ مُّحْضَرُونَ

Transliteration lā yastaṭīʿūna naṣrahum wahum lahum jundun muḥ'ḍarūna

Yoruba Wọn kò sì lè ṣe àrànṣe fún wọn; ṣebí àwọn òrìṣà ni ọmọ ogun tí (àwọn mọlāika) máa kó wá sínú Iná fún àwọn abọ̀rìṣà (láti fi jẹ wọ́n níyà).1

Verse 76

فَلَا يَحْزُنكَ قَوْلُهُمْ ۘ إِنَّا نَعْلَمُ مَا يُسِرُّونَ وَمَا يُعْلِنُونَ

Transliteration falā yaḥzunka qawluhum innā naʿlamu mā yusirrūna wamā yuʿ'linūna

Yoruba Nítorí náà, má ṣe jẹ́ kí ọ̀rọ̀ wọn bà ọ́ nínú jẹ́. Dájúdájú Àwa mọ ohun tí wọ́n ń fi pamọ́ àti ohun tí wọ́n ń ṣàfi hàn rẹ̀.

Verse 77

أَوَلَمْ يَرَ ٱلْإِنسَـٰنُ أَنَّا خَلَقْنَـٰهُ مِن نُّطْفَةٍ فَإِذَا هُوَ خَصِيمٌ مُّبِينٌ

Transliteration awalam yara l-insānu annā khalaqnāhu min nuṭ'fatin fa-idhā huwa khaṣīmun mubīnun

Yoruba Ṣé ènìyàn kò wòye pé dájúdájú Àwa l’A ṣẹ̀dá rẹ̀ láti inú àtọ̀? (Ṣebí lẹ́yìn) ìgbà náà l’ó di alátakò pọ́nńbélé.

Verse 78

وَضَرَبَ لَنَا مَثَلًا وَنَسِىَ خَلْقَهُۥ ۖ قَالَ مَن يُحْىِ ٱلْعِظَـٰمَ وَهِىَ رَمِيمٌ

Transliteration waḍaraba lanā mathalan wanasiya khalqahu qāla man yuḥ'yī l-ʿiẓāma wahiya ramīmun

Yoruba Àti pé ó fi àkàwé lélẹ̀ nípa Wa.Ó sì gbàgbé ìṣẹ̀dá rẹ̀. Ó wí pé: “Ta ni Ó máa sọ egungun di alààyè nígbà tí ó ti kẹfun?”

Verse 79

قُلْ يُحْيِيهَا ٱلَّذِىٓ أَنشَأَهَآ أَوَّلَ مَرَّةٍ ۖ وَهُوَ بِكُلِّ خَلْقٍ عَلِيمٌ

Transliteration qul yuḥ'yīhā alladhī ansha-ahā awwala marratin wahuwa bikulli khalqin ʿalīmun

Yoruba Sọ pé: “Ẹni tí Ó ṣẹ̀dá rẹ̀ nígbà àkọ́kọ́ l’Ó máa sọ ọ́ di alààyè. Òun sì ni Onímọ̀ nípa gbogbo ẹ̀dá.

Verse 80

ٱلَّذِى جَعَلَ لَكُم مِّنَ ٱلشَّجَرِ ٱلْأَخْضَرِ نَارًا فَإِذَآ أَنتُم مِّنْهُ تُوقِدُونَ

Transliteration alladhī jaʿala lakum mina l-shajari l-akhḍari nāran fa-idhā antum min'hu tūqidūna

Yoruba (Òun ni) Ẹni tí Ó mú iná jáde fún yín láti ara igi tútù. Ẹ sì ń fi dáná.

Verse 81

أَوَلَيْسَ ٱلَّذِى خَلَقَ ٱلسَّمَـٰوَٰتِ وَٱلْأَرْضَ بِقَـٰدِرٍ عَلَىٰٓ أَن يَخْلُقَ مِثْلَهُم ۚ بَلَىٰ وَهُوَ ٱلْخَلَّـٰقُ ٱلْعَلِيمُ

Transliteration awalaysa alladhī khalaqa l-samāwāti wal-arḍa biqādirin ʿalā an yakhluqa mith'lahum balā wahuwa l-khalāqu l-ʿalīmu

Yoruba Ǹjẹ́ Ẹni tí Ó ṣẹ̀dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ kò ní agbára láti dá irú wọn (mìíràn) bí? Bẹ́ẹ̀ ni (Ó ní agbára). Òun sì ni Ẹlẹ́dàá, Onímọ̀.

Verse 82

إِنَّمَآ أَمْرُهُۥٓ إِذَآ أَرَادَ شَيْـًٔا أَن يَقُولَ لَهُۥ كُن فَيَكُونُ

Transliteration innamā amruhu idhā arāda shayan an yaqūla lahu kun fayakūnu

Yoruba Àṣẹ Rẹ̀ nígbà tí Ó bá gbèrò kiní kan ni pé, Ó máa sọ fún un pé “Jẹ́ bẹ́ẹ̀.” Ó sì máa jẹ́ bẹ́ẹ̀.

Verse 83

فَسُبْحَـٰنَ ٱلَّذِى بِيَدِهِۦ مَلَكُوتُ كُلِّ شَىْءٍ وَإِلَيْهِ تُرْجَعُونَ

Transliteration fasub'ḥāna alladhī biyadihi malakūtu kulli shayin wa-ilayhi tur'jaʿūna

Yoruba Nítorí náà, mímọ́ ni fún Ẹni tí ìjọba gbogbo n̄ǹkan wà ní ọwọ́ Rẹ̀. Ọ̀dọ̀ Rẹ̀ sì ni wọn yóò da yín padà sí.

Read Surah Ya-Sin in another language

All languages

All 114 surahs in Yoruba: the Qur’an in Yoruba.

Learn it in MyDugsi

Yoruba translation: Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni, from Quran.com. Transliteration: Quran.com. Recitation: Mishary Alafasy, from EveryAyah.com. MyDugsi is a learning aid, not a replacement for a qualified teacher.