Surah Al-Mutaffifin in Yoruba: translation and audio
Surah 83 · المطففين · The Defrauding · 36 verses
Surah Al-Mutaffifin verse by verse: the Arabic with a recitation you can repeat, the transliteration, and the Yoruba translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni. For the meaning of every word, see Surah Al-Mutaffifin word by word in English.
Verse 1
وَيْلٌ لِّلْمُطَفِّفِينَ
Transliteration waylun lil'muṭaffifīna
Yoruba Ègbé ni fún àwọn olùdín-òṣùwọ̀n-kù,
Verse 2
ٱلَّذِينَ إِذَا ٱكْتَالُوا۟ عَلَى ٱلنَّاسِ يَسْتَوْفُونَ
Transliteration alladhīna idhā ik'tālū ʿalā l-nāsi yastawfūna
Yoruba àwọn (òǹtajà) tó jẹ́ pé nígbà tí wọ́n bá wọn n̄ǹkan lọ́dọ̀ àwọn ènìyàn,wọ́n á gbà á ní ẹ̀kún,
Verse 3
وَإِذَا كَالُوهُمْ أَو وَّزَنُوهُمْ يُخْسِرُونَ
Transliteration wa-idhā kālūhum aw wazanūhum yukh'sirūna
Yoruba nígbà tí àwọn (òǹtajà náà) bá sì lo ìwọ̀n fún àwọn (òǹrajà) tàbí lo òṣùwọ̀n fún wọn, wọn yóò dín in kù.
Verse 4
أَلَا يَظُنُّ أُو۟لَـٰٓئِكَ أَنَّهُم مَّبْعُوثُونَ
Transliteration alā yaẓunnu ulāika annahum mabʿūthūna
Yoruba Ṣé àwọn wọ̀nyẹn kò mọ̀ dájú pé dájúdájú A máa gbé wọn dìde
Verse 5
لِيَوْمٍ عَظِيمٍ
Transliteration liyawmin ʿaẓīmin
Yoruba ní Ọjọ́ ńlá kan?
Verse 6
يَوْمَ يَقُومُ ٱلنَّاسُ لِرَبِّ ٱلْعَـٰلَمِينَ
Transliteration yawma yaqūmu l-nāsu lirabbi l-ʿālamīna
Yoruba Ní ọjọ́ tí àwọn ènìyàn yóò dìde dúró fún Olúwa gbogbo ẹ̀dá.
Verse 7
كَلَّآ إِنَّ كِتَـٰبَ ٱلْفُجَّارِ لَفِى سِجِّينٍ
Transliteration kallā inna kitāba l-fujāri lafī sijjīnin
Yoruba Ní ti òdodo dájúdájú ìwé iṣẹ́ àwọn ẹni burúkú (tó ń dín òṣùwọ̀n kù) kúkú máa wà nínú Sijjīn.
Verse 8
وَمَآ أَدْرَىٰكَ مَا سِجِّينٌ
Transliteration wamā adrāka mā sijjīnun
Yoruba Kí sì l’ó mú ọ mọ ohun tó ń jẹ́ Sijjīn!
Verse 9
كِتَـٰبٌ مَّرْقُومٌ
Transliteration kitābun marqūmun
Yoruba Ìwé tí wọ́n ti kọ iṣẹ́ aburú ẹ̀dá sínú rẹ̀ (tí wọ́n sì fi pamọ́ sínú ilẹ̀ keje ni Sijjīn).
Verse 10
وَيْلٌ يَوْمَئِذٍ لِّلْمُكَذِّبِينَ
Transliteration waylun yawma-idhin lil'mukadhibīna
Yoruba Ní ọjọ́ yẹn, ègbé ni fún àwọn olùpe-òdodo- nírọ́,
Verse 11
ٱلَّذِينَ يُكَذِّبُونَ بِيَوْمِ ٱلدِّينِ
Transliteration alladhīna yukadhibūna biyawmi l-dīni
Yoruba àwọn tó ń pe Ọjọ́ ẹ̀san ní irọ́.
Verse 12
وَمَا يُكَذِّبُ بِهِۦٓ إِلَّا كُلُّ مُعْتَدٍ أَثِيمٍ
Transliteration wamā yukadhibu bihi illā kullu muʿ'tadin athīmin
Yoruba Kò sì sí ẹni tó ń pè é ní irọ́ àyàfi gbogbo alákọyọ, ẹlẹ́ṣẹ̀.
Verse 13
إِذَا تُتْلَىٰ عَلَيْهِ ءَايَـٰتُنَا قَالَ أَسَـٰطِيرُ ٱلْأَوَّلِينَ
Transliteration idhā tut'lā ʿalayhi āyātunā qāla asāṭīru l-awalīna
Yoruba Nígbà tí wọ́n bá ń ké àwọn āyah Wa fún un, ó máa wí pé: “Àwọn àkọsílẹ̀ àlọ́ àwọn ẹni àkọ́kọ́ (nìwọ̀nyí).”
Verse 14
كَلَّا ۖ بَلْ ۜ رَانَ عَلَىٰ قُلُوبِهِم مَّا كَانُوا۟ يَكْسِبُونَ
Transliteration kallā bal rāna ʿalā qulūbihim mā kānū yaksibūna
Yoruba Rárá (al-Ƙur’ān kì í ṣe àkọsílẹ̀ àlọ́ àwọn ẹni àkọ́kọ́) bí kò ṣe pé ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́ aburú l’ó jọba lórí ọkàn wọn.
Verse 15
كَلَّآ إِنَّهُمْ عَن رَّبِّهِمْ يَوْمَئِذٍ لَّمَحْجُوبُونَ
Transliteration kallā innahum ʿan rabbihim yawma-idhin lamaḥjūbūna
Yoruba Rárá (kò rí bí wọ́n ṣe rò ó sí sẹ́), dájúdájú wọn yóò wà nínú gàgá, wọn kò sì níí rí Olúwa wọn ní ọjọ́ yẹn.
Verse 16
ثُمَّ إِنَّهُمْ لَصَالُوا۟ ٱلْجَحِيمِ
Transliteration thumma innahum laṣālū l-jaḥīmi
Yoruba Lẹ́yìn náà, dájúdájú wọn yóò wọ inú iná Jẹhīm.
Verse 17
ثُمَّ يُقَالُ هَـٰذَا ٱلَّذِى كُنتُم بِهِۦ تُكَذِّبُونَ
Transliteration thumma yuqālu hādhā alladhī kuntum bihi tukadhibūna
Yoruba Lẹ́yìn náà, wọ́n máa sọ (fún wọn) pe: “Èyí ni ohun tí ẹ̀ ń pè ní irọ́.”
Verse 18
كَلَّآ إِنَّ كِتَـٰبَ ٱلْأَبْرَارِ لَفِى عِلِّيِّينَ
Transliteration kallā inna kitāba l-abrāri lafī ʿilliyyīna
Yoruba Ní ti òdodo, dájúdájú ìwé iṣẹ́ àwọn ẹni rere wà nínú ‘illiyyūn.
Verse 19
وَمَآ أَدْرَىٰكَ مَا عِلِّيُّونَ
Transliteration wamā adrāka mā ʿilliyyūna
Yoruba Kí sì l’ó mú ọ mọ ohun tó ń jẹ́ ‘illiyyūn!
Verse 20
كِتَـٰبٌ مَّرْقُومٌ
Transliteration kitābun marqūmun
Yoruba Ìwé tí wọ́n ti kọ iṣẹ́ rere ẹ̀dá sínú rẹ̀ (tí wọ́n sì fi pamọ́ sí òkè sánmọ̀ ni ‘illiyyūn).
Verse 21
يَشْهَدُهُ ٱلْمُقَرَّبُونَ
Transliteration yashhaduhu l-muqarabūna
Yoruba Àwọn (mọlāika) tí wọ́n súnmọ́ Allāhu ń jẹ́rìí sí i.
Verse 22
إِنَّ ٱلْأَبْرَارَ لَفِى نَعِيمٍ
Transliteration inna l-abrāra lafī naʿīmin
Yoruba Dájúdájú àwọn ẹni rere máa wà nínú ìgbádùn.
Verse 23
عَلَى ٱلْأَرَآئِكِ يَنظُرُونَ
Transliteration ʿalā l-arāiki yanẓurūna
Yoruba Wọn yóò máa wòran lórí àwọn ibùsùn.
Verse 24
تَعْرِفُ فِى وُجُوهِهِمْ نَضْرَةَ ٱلنَّعِيمِ
Transliteration taʿrifu fī wujūhihim naḍrata l-naʿīmi
Yoruba Ìwọ yóò dá ìtutù ojú ìgbádùn mọ̀ nínú ojú wọn.
Verse 25
يُسْقَوْنَ مِن رَّحِيقٍ مَّخْتُومٍ
Transliteration yus'qawna min raḥīqin makhtūmin
Yoruba Wọn yóò máa fún wọn mu nínú ọtí onídèérí.
Verse 26
خِتَـٰمُهُۥ مِسْكٌ ۚ وَفِى ذَٰلِكَ فَلْيَتَنَافَسِ ٱلْمُتَنَـٰفِسُونَ
Transliteration khitāmuhu mis'kun wafī dhālika falyatanāfasi l-mutanāfisūna
Yoruba Àlùmísìkí ni (òórùn) ìparí rẹ̀. Kí àwọn alápàáǹtètè ṣàpáǹtètè nínú ìyẹn.
Verse 27
وَمِزَاجُهُۥ مِن تَسْنِيمٍ
Transliteration wamizājuhu min tasnīmin
Yoruba Tẹsnīm ni wọ́n yóò máa pòpọ̀ (mọ́ ọtí náà).
Verse 28
عَيْنًا يَشْرَبُ بِهَا ٱلْمُقَرَّبُونَ
Transliteration ʿaynan yashrabu bihā l-muqarabūna
Yoruba (Tẹsnīm ni) omi ìṣẹ́lẹ̀rú kan, tí àwọn olùsúnmọ́ (Allāhu) yóò máa mu.
Verse 29
إِنَّ ٱلَّذِينَ أَجْرَمُوا۟ كَانُوا۟ مِنَ ٱلَّذِينَ ءَامَنُوا۟ يَضْحَكُونَ
Transliteration inna alladhīna ajramū kānū mina alladhīna āmanū yaḍḥakūna
Yoruba Dájúdájú àwọn tó dẹ́ṣẹ̀, wọ́n máa ń fi àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo rẹ́rìn-ín.
Verse 30
وَإِذَا مَرُّوا۟ بِهِمْ يَتَغَامَزُونَ
Transliteration wa-idhā marrū bihim yataghāmazūna
Yoruba Nígbà tí wọ́n bá gba ẹ̀gbẹ́ wọn kọjá, (àwọn olùdẹ́ṣẹ̀) yóò máa ṣẹ́jú síra wọn ní ti yẹ̀yẹ́.
Verse 31
وَإِذَا ٱنقَلَبُوٓا۟ إِلَىٰٓ أَهْلِهِمُ ٱنقَلَبُوا۟ فَكِهِينَ
Transliteration wa-idhā inqalabū ilā ahlihimu inqalabū fakihīna
Yoruba Nígbà tí wọ́n bá sì padà sí ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn wọn, wọ́n á padà tí wọn yóò máa ṣe fáàrí.
Verse 32
وَإِذَا رَأَوْهُمْ قَالُوٓا۟ إِنَّ هَـٰٓؤُلَآءِ لَضَآلُّونَ
Transliteration wa-idhā ra-awhum qālū inna hāulāi laḍāllūna
Yoruba Àti pé nígbà tí wọ́n bá rí (àwọn onígbàgbọ́ òdodo) wọ́n á wí pé: “Dájúdájú àwọn wọ̀nyí ni olùṣìnà.”
Verse 33
وَمَآ أُرْسِلُوا۟ عَلَيْهِمْ حَـٰفِظِينَ
Transliteration wamā ur'silū ʿalayhim ḥāfiẓīna
Yoruba Àwa kò sì rán wọn ní iṣẹ́ olùṣọ́ sí wọn.
Verse 34
فَٱلْيَوْمَ ٱلَّذِينَ ءَامَنُوا۟ مِنَ ٱلْكُفَّارِ يَضْحَكُونَ
Transliteration fal-yawma alladhīna āmanū mina l-kufāri yaḍḥakūna
Yoruba Nítorí náà, ní òní àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo yóò fi àwọn aláìgbàgbọ́ rẹ́rìn-ín.
Verse 35
عَلَى ٱلْأَرَآئِكِ يَنظُرُونَ
Transliteration ʿalā l-arāiki yanẓurūna
Yoruba Wọn yóò máa wòran lórí àwọn ibùsùn.
Verse 36
هَلْ ثُوِّبَ ٱلْكُفَّارُ مَا كَانُوا۟ يَفْعَلُونَ
Transliteration hal thuwwiba l-kufāru mā kānū yafʿalūna
Yoruba Ṣebí wọ́n ti fi ohun tí àwọn aláìgbàgbọ́ ń ṣe níṣẹ́ san wọ́n lẹ́san (báyìí)?
Read Surah Al-Mutaffifin in another language
- English (word by word)
- Albanian
- Amazigh
- Amharic
- Assamese
- Azerbaijani
- Bambara
- Bangla
- Bosnian
- Bulgarian
- Chechen
- Chinese
- Czech
- Dari
- Dhivehi
- Dutch
- Finnish
- French
- German
- Gujarati
- Hausa
- Hebrew
- Hindi
- Indonesian
- Italian
- Japanese
- Kannada
- Kazakh
- Khmer
- Kinyarwanda
- Korean
- Kurdish
- Luganda
- Malay
- Malayalam
- Maranao
- Marathi
- Nepali
- Norwegian
- Oromo
- Pashto
- Persian
- Polish
- Portuguese
- Romanian
- Russian
- Sindhi
- Sinhala
- Somali
- Spanish
- Swahili
- Swedish
- Tagalog
- Tajik
- Tamil
- Tatar
- Telugu
- Thai
- Turkish
- Ukrainian
- Urdu
- Uyghur
- Uzbek
- Vietnamese
- Yao
All 114 surahs in Yoruba: the Qur’an in Yoruba.
Yoruba translation: Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni, from Quran.com. Transliteration: Quran.com. Recitation: Mishary Alafasy, from EveryAyah.com. MyDugsi is a learning aid, not a replacement for a qualified teacher.