Surah Az-Zukhruf in Yoruba: translation and audio
Surah 43 · الزخرف · The Ornaments of Gold · 89 verses
Surah Az-Zukhruf verse by verse: the Arabic with a recitation you can repeat, the transliteration, and the Yoruba translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni. For the meaning of every word, see Surah Az-Zukhruf word by word in English.
Verse 1
حمٓ
Transliteration hha-meem
Yoruba Hā mīm. (Allāhu ló mọ ohun tí Ó gbàlérò pẹ̀lú àwọn háràfí náà.)1
Verse 2
وَٱلْكِتَـٰبِ ٱلْمُبِينِ
Transliteration wal-kitābi l-mubīni
Yoruba (Allāhu) fi Tírà tó ń yanjú ọ̀rọ̀ ẹ̀dá búra.
Verse 3
إِنَّا جَعَلْنَـٰهُ قُرْءَٰنًا عَرَبِيًّا لَّعَلَّكُمْ تَعْقِلُونَ
Transliteration innā jaʿalnāhu qur'ānan ʿarabiyyan laʿallakum taʿqilūna
Yoruba Dájúdájú Àwa se é ní al-Ƙur’ān (n̄ǹkan kíké) ní èdè Lárúbáwá nítorí kí ẹ lè ṣe làákàyè.
Verse 4
وَإِنَّهُۥ فِىٓ أُمِّ ٱلْكِتَـٰبِ لَدَيْنَا لَعَلِىٌّ حَكِيمٌ
Transliteration wa-innahu fī ummi l-kitābi ladaynā laʿaliyyun ḥakīmun
Yoruba Àti pé dájúdájú nínú Tírà Ìpìlẹ̀ tó wà lọ́dọ̀ Wa, al-Ƙur’ān mà ga, ó sì kún fún ọgbọ́n.
Verse 5
أَفَنَضْرِبُ عَنكُمُ ٱلذِّكْرَ صَفْحًا أَن كُنتُمْ قَوْمًا مُّسْرِفِينَ
Transliteration afanaḍribu ʿankumu l-dhik'ra ṣafḥan an kuntum qawman mus'rifīna
Yoruba Ṣé kí Á ká Tírà Ìrántí (al-Ƙur’ān) kúrò nílẹ̀ fún yín pátápátá (kí Á máa wò yín ní ìran) nítorí pé, ẹ jẹ́ ìjọ alákọyọ?
Verse 6
وَكَمْ أَرْسَلْنَا مِن نَّبِىٍّ فِى ٱلْأَوَّلِينَ
Transliteration wakam arsalnā min nabiyyin fī l-awalīna
Yoruba Mélòó mélòó nínú àwọn Ànábì tí A ti rán sí àwọn ẹni àkọ́kọ́.
Verse 7
وَمَا يَأْتِيهِم مِّن نَّبِىٍّ إِلَّا كَانُوا۟ بِهِۦ يَسْتَهْزِءُونَ
Transliteration wamā yatīhim min nabiyyin illā kānū bihi yastahziūna
Yoruba Kò sí Ànábì kan tí ó wá bá wọn àyàfi kí wọ́n máa fi ṣe yẹ̀yẹ́.
Verse 8
فَأَهْلَكْنَآ أَشَدَّ مِنْهُم بَطْشًا وَمَضَىٰ مَثَلُ ٱلْأَوَّلِينَ
Transliteration fa-ahlaknā ashadda min'hum baṭshan wamaḍā mathalu l-awalīna
Yoruba Nítorí náà, A ti pa àwọn tó ní agbára ju àwọn (wọ̀nyí) rẹ́. Àpèjúwe (ìparun) àwọn ẹni àkọ́kọ́ sì ti ṣíwájú.
Verse 9
وَلَئِن سَأَلْتَهُم مَّنْ خَلَقَ ٱلسَّمَـٰوَٰتِ وَٱلْأَرْضَ لَيَقُولُنَّ خَلَقَهُنَّ ٱلْعَزِيزُ ٱلْعَلِيمُ
Transliteration wala-in sa-altahum man khalaqa l-samāwāti wal-arḍa layaqūlunna khalaqahunna l-ʿazīzu l-ʿalīmu
Yoruba Tí o bá kúkú bi wọ́n léèrè pé: “Ta ni Ó dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀?”, dájúdájú wọ́n á wí pé: “Ẹni tó dá wọn ni Alágbára, Onímọ̀;
Verse 10
ٱلَّذِى جَعَلَ لَكُمُ ٱلْأَرْضَ مَهْدًا وَجَعَلَ لَكُمْ فِيهَا سُبُلًا لَّعَلَّكُمْ تَهْتَدُونَ
Transliteration alladhī jaʿala lakumu l-arḍa mahdan wajaʿala lakum fīhā subulan laʿallakum tahtadūna
Yoruba Ẹni tí Ó ṣe ilẹ̀ ní ìtẹ́ fún yín. Ó sì fi àwọn ojú ọ̀nà sínú rẹ̀ fún yín nítorí kí ẹ lè mọ̀nà;
Verse 11
وَٱلَّذِى نَزَّلَ مِنَ ٱلسَّمَآءِ مَآءًۢ بِقَدَرٍ فَأَنشَرْنَا بِهِۦ بَلْدَةً مَّيْتًا ۚ كَذَٰلِكَ تُخْرَجُونَ
Transliteration wa-alladhī nazzala mina l-samāi māan biqadarin fa-ansharnā bihi baldatan maytan kadhālika tukh'rajūna
Yoruba Ẹni tí Ó ń sọ omi kalẹ̀ láti sánmọ̀ níwọ̀n-níwọ̀n. Ó sì ń fi sọ òkú ilẹ̀ di àyè ilẹ̀. Báyẹn náà ni wọn yóò ṣe mu yín jáde.
Verse 12
وَٱلَّذِى خَلَقَ ٱلْأَزْوَٰجَ كُلَّهَا وَجَعَلَ لَكُم مِّنَ ٱلْفُلْكِ وَٱلْأَنْعَـٰمِ مَا تَرْكَبُونَ
Transliteration wa-alladhī khalaqa l-azwāja kullahā wajaʿala lakum mina l-ful'ki wal-anʿāmi mā tarkabūna
Yoruba Ẹni tí Ó ṣẹ̀dá gbogbo n̄ǹkan ní oríṣiríṣi.Ó sì ṣe n̄ǹkan tí ẹ̀ ń gùn fún yín láti ara àwọn ọkọ̀ ojú-omi àti àwọn ẹran-ọ̀sìn.
Verse 13
لِتَسْتَوُۥا۟ عَلَىٰ ظُهُورِهِۦ ثُمَّ تَذْكُرُوا۟ نِعْمَةَ رَبِّكُمْ إِذَا ٱسْتَوَيْتُمْ عَلَيْهِ وَتَقُولُوا۟ سُبْحَـٰنَ ٱلَّذِى سَخَّرَ لَنَا هَـٰذَا وَمَا كُنَّا لَهُۥ مُقْرِنِينَ
Transliteration litastawū ʿalā ẓuhūrihi thumma tadhkurū niʿ'mata rabbikum idhā is'tawaytum ʿalayhi wataqūlū sub'ḥāna alladhī sakhara lanā hādhā wamā kunnā lahu muq'rinīna
Yoruba Nítorí kí ẹ lè jókòó dáadáa sẹ́yìn rẹ̀, lẹ́yìn náà kí ẹ lè ṣe ìrántí ìdẹ̀ra Olúwa yín nígbà tí ẹ bá jókòó dáadáa tán sórí rẹ̀, kí ẹ sì sọ pé: “Mímọ́ ni fún Ẹni tí Ó rọ èyí fún wa, kì í ṣe pé a jẹ́ alágbára lórí rẹ̀.
Verse 14
وَإِنَّآ إِلَىٰ رَبِّنَا لَمُنقَلِبُونَ
Transliteration wa-innā ilā rabbinā lamunqalibūna
Yoruba Àti pé dájúdájú ọ̀dọ̀ Olúwa wa ni àwa yóò padà sí.”
Verse 15
وَجَعَلُوا۟ لَهُۥ مِنْ عِبَادِهِۦ جُزْءًا ۚ إِنَّ ٱلْإِنسَـٰنَ لَكَفُورٌ مُّبِينٌ
Transliteration wajaʿalū lahu min ʿibādihi juz'an inna l-insāna lakafūrun mubīnun
Yoruba Wọ́n fi ìpín kan nínú àwọn ẹrúsìn (Allāhu) tì sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀ (ní ti ọmọ bíbí). Dájúdájú ènìyàn ni aláìmoore pọ́nńbélé.
Verse 16
أَمِ ٱتَّخَذَ مِمَّا يَخْلُقُ بَنَاتٍ وَأَصْفَىٰكُم بِٱلْبَنِينَ
Transliteration ami ittakhadha mimmā yakhluqu banātin wa-aṣfākum bil-banīna
Yoruba Tàbí (ẹ̀yin ń wí pé): “Ó mú nínú n̄ǹkan tí Ó dá ní ọmọbìnrin (fúnra Rẹ̀). Ó sì fi àwọn ọmọkùnrin ṣa ẹ̀yin lẹ́ṣà.”
Verse 17
وَإِذَا بُشِّرَ أَحَدُهُم بِمَا ضَرَبَ لِلرَّحْمَـٰنِ مَثَلًا ظَلَّ وَجْهُهُۥ مُسْوَدًّا وَهُوَ كَظِيمٌ
Transliteration wa-idhā bushira aḥaduhum bimā ḍaraba lilrraḥmāni mathalan ẓalla wajhuhu mus'waddan wahuwa kaẓīmun
Yoruba Nígbà tí wọ́n bá fún ẹnì kan nínú wọn ní ìró ìdùnnú ohun tí ó fi ṣe àpẹ̀ẹrẹ fún Àjọkẹ́-ayé, ojú rẹ̀ máa dúdú wá (pé òun bí ọmọbìnrin).Ó sì máa kún fún ìbànújẹ́.
Verse 18
أَوَمَن يُنَشَّؤُا۟ فِى ٱلْحِلْيَةِ وَهُوَ فِى ٱلْخِصَامِ غَيْرُ مُبِينٍ
Transliteration awaman yunasha-u fī l-ḥil'yati wahuwa fī l-khiṣāmi ghayru mubīnin
Yoruba Ṣé ẹni tí wọ́n ń tọ́ nínú ọ̀ṣọ́ (tí ó ń to ọ̀ṣọ́ mọ́ra), tí kò sì lè bọ́ sí gban̄gba níbi ìjà (ni ẹ̀ ń pè ní ọmọ Àjọkẹ́-ayé)!?
Verse 19
وَجَعَلُوا۟ ٱلْمَلَـٰٓئِكَةَ ٱلَّذِينَ هُمْ عِبَـٰدُ ٱلرَّحْمَـٰنِ إِنَـٰثًا ۚ أَشَهِدُوا۟ خَلْقَهُمْ ۚ سَتُكْتَبُ شَهَـٰدَتُهُمْ وَيُسْـَٔلُونَ
Transliteration wajaʿalū l-malāikata alladhīna hum ʿibādu l-raḥmāni ināthan ashahidū khalqahum satuk'tabu shahādatuhum wayus'alūna
Yoruba Àwọn mọlāika, àwọn tó jẹ́ ẹrúsìn Àjọkẹ́-ayé, wọ́n tún sọ wọ́n di ọmọbìnrin! Ṣé wọ́n fojú rí ìṣẹ̀dá wọn ni? Wọ́n máa ṣàkọsílẹ̀ ohun tí wọ́n fojú rí. Wọ́n sì máa bi wọ́n léèrè (nípa rẹ̀).
Verse 20
وَقَالُوا۟ لَوْ شَآءَ ٱلرَّحْمَـٰنُ مَا عَبَدْنَـٰهُم ۗ مَّا لَهُم بِذَٰلِكَ مِنْ عِلْمٍ ۖ إِنْ هُمْ إِلَّا يَخْرُصُونَ
Transliteration waqālū law shāa l-raḥmānu mā ʿabadnāhum mā lahum bidhālika min ʿil'min in hum illā yakhruṣūna
Yoruba Wọ́n tún wí pé: “Tí Àjọkẹ́-ayé bá fẹ́, àwa ìbá tí jọ́sìn fún wọn.” Kò sí ìmọ̀ kan fún wọn nípa ìyẹn. Wọn kò sì jẹ́ kiní kan bí kò ṣe pé wọ́n ń parọ́.
Verse 21
أَمْ ءَاتَيْنَـٰهُمْ كِتَـٰبًا مِّن قَبْلِهِۦ فَهُم بِهِۦ مُسْتَمْسِكُونَ
Transliteration am ātaynāhum kitāban min qablihi fahum bihi mus'tamsikūna
Yoruba Tàbí A ti fún wọn ní Tírà kan ṣíwájú al-Ƙur’ān, tí wọ́n ń lò ní ẹ̀rí?
Verse 22
بَلْ قَالُوٓا۟ إِنَّا وَجَدْنَآ ءَابَآءَنَا عَلَىٰٓ أُمَّةٍ وَإِنَّا عَلَىٰٓ ءَاثَـٰرِهِم مُّهْتَدُونَ
Transliteration bal qālū innā wajadnā ābāanā ʿalā ummatin wa-innā ʿalā āthārihim muh'tadūna
Yoruba Rárá. Wọ́n wí pé: “Dájúdájú àwa bá àwọn bàbá wa lórí ẹ̀sìn kan. Dájúdájú àwa sì ni olùmọ̀nà lórí orípa wọn.”1
Verse 23
وَكَذَٰلِكَ مَآ أَرْسَلْنَا مِن قَبْلِكَ فِى قَرْيَةٍ مِّن نَّذِيرٍ إِلَّا قَالَ مُتْرَفُوهَآ إِنَّا وَجَدْنَآ ءَابَآءَنَا عَلَىٰٓ أُمَّةٍ وَإِنَّا عَلَىٰٓ ءَاثَـٰرِهِم مُّقْتَدُونَ
Transliteration wakadhālika mā arsalnā min qablika fī qaryatin min nadhīrin illā qāla mut'rafūhā innā wajadnā ābāanā ʿalā ummatin wa-innā ʿalā āthārihim muq'tadūna
Yoruba Bákan náà, Àwa kò rán olùkìlọ̀ kan sí ìlú kan ṣíwájú rẹ, àyàfi kí àwọn onígbẹdẹmukẹ ìlú náà wí pé: “Dájúdájú àwa bá àwọn bàbá wa lórí ẹ̀sìn kan. Dájúdájú àwa sì ni olùtẹ̀lé wọn lórí orípa wọn.”
Verse 24
۞ قَـٰلَ أَوَلَوْ جِئْتُكُم بِأَهْدَىٰ مِمَّا وَجَدتُّمْ عَلَيْهِ ءَابَآءَكُمْ ۖ قَالُوٓا۟ إِنَّا بِمَآ أُرْسِلْتُم بِهِۦ كَـٰفِرُونَ
Transliteration qāla awalaw ji'tukum bi-ahdā mimmā wajadttum ʿalayhi ābāakum qālū innā bimā ur'sil'tum bihi kāfirūna
Yoruba (Olùkìlọ̀) sì sọ pé: “Ǹjẹ́ èmi kò ti mú wá fún yín ohun tí ó jẹ́ ìmọ̀nà jùlọ sí ohun tí ẹ bá àwọn bàbá yín lórí rẹ̀?” Wọ́n wí pé: “Dájúdájú àwa jẹ́ aláìgbàgbọ́ nínú ohun tí wọ́n fi ran yín níṣẹ́.”
Verse 25
فَٱنتَقَمْنَا مِنْهُمْ ۖ فَٱنظُرْ كَيْفَ كَانَ عَـٰقِبَةُ ٱلْمُكَذِّبِينَ
Transliteration fa-intaqamnā min'hum fa-unẓur kayfa kāna ʿāqibatu l-mukadhibīna
Yoruba Nítorí náà, A gbẹ̀san lára wọn. Wo bí ìkángun àwọn tó pe òdodo ní irọ́ ti rí!
Verse 26
وَإِذْ قَالَ إِبْرَٰهِيمُ لِأَبِيهِ وَقَوْمِهِۦٓ إِنَّنِى بَرَآءٌ مِّمَّا تَعْبُدُونَ
Transliteration wa-idh qāla ib'rāhīmu li-abīhi waqawmihi innanī barāon mimmā taʿbudūna
Yoruba (Rántí) nígbà tí (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm sọ fún bàbá rẹ̀ àti àwọn ènìyàn rẹ̀ pé: “Dájúdájú èmi yọwọ́ yọsẹ̀ kúrò nínú ohun tí ẹ̀ ń jọ́sìn fún.
Verse 27
إِلَّا ٱلَّذِى فَطَرَنِى فَإِنَّهُۥ سَيَهْدِينِ
Transliteration illā alladhī faṭaranī fa-innahu sayahdīni
Yoruba Àfi Ẹni tí Ó ṣẹ̀dá mi. Dájúdájú Òun l’Ó máa fi ọ̀nà tààrà mọ̀ mí.”
Verse 28
وَجَعَلَهَا كَلِمَةًۢ بَاقِيَةً فِى عَقِبِهِۦ لَعَلَّهُمْ يَرْجِعُونَ
Transliteration wajaʿalahā kalimatan bāqiyatan fī ʿaqibihi laʿallahum yarjiʿūna
Yoruba Allāhu sì ṣe é ní ọ̀rọ̀ kan tó máa wà títí láéláé láààrin àwọn àrọ́mọdọ́mọ rẹ̀ nítorí kí wọ́n lè ṣẹ́rí padà (síbi òdodo).1
Verse 29
بَلْ مَتَّعْتُ هَـٰٓؤُلَآءِ وَءَابَآءَهُمْ حَتَّىٰ جَآءَهُمُ ٱلْحَقُّ وَرَسُولٌ مُّبِينٌ
Transliteration bal mattaʿtu hāulāi waābāahum ḥattā jāahumu l-ḥaqu warasūlun mubīnun
Yoruba Ṣùgbọ́n Mo fún àwọn wọ̀nyí àti àwọn bàbá wọn ní ìgbádùn ayé títí òdodo àti Òjíṣẹ́ pọ́nńbélé fi dé bá wọn.
Verse 30
وَلَمَّا جَآءَهُمُ ٱلْحَقُّ قَالُوا۟ هَـٰذَا سِحْرٌ وَإِنَّا بِهِۦ كَـٰفِرُونَ
Transliteration walammā jāahumu l-ḥaqu qālū hādhā siḥ'run wa-innā bihi kāfirūna
Yoruba Nígbà tí òdodo dé bá wọn, wọ́n wí pé: “Idán ni èyí; dájúdájú àwa kò sì níí gbà á gbọ́.”
Verse 31
وَقَالُوا۟ لَوْلَا نُزِّلَ هَـٰذَا ٱلْقُرْءَانُ عَلَىٰ رَجُلٍ مِّنَ ٱلْقَرْيَتَيْنِ عَظِيمٍ
Transliteration waqālū lawlā nuzzila hādhā l-qur'ānu ʿalā rajulin mina l-qaryatayni ʿaẓīmin
Yoruba Wọ́n tún wí pé: “Kí ni kò jẹ́ kí Wọ́n sọ al-Ƙur’ān yìí kalẹ̀ fún ọkùnrin ńlá kan nínú àwọn ìlú méjèèjì?”
Verse 32
أَهُمْ يَقْسِمُونَ رَحْمَتَ رَبِّكَ ۚ نَحْنُ قَسَمْنَا بَيْنَهُم مَّعِيشَتَهُمْ فِى ٱلْحَيَوٰةِ ٱلدُّنْيَا ۚ وَرَفَعْنَا بَعْضَهُمْ فَوْقَ بَعْضٍ دَرَجَـٰتٍ لِّيَتَّخِذَ بَعْضُهُم بَعْضًا سُخْرِيًّا ۗ وَرَحْمَتُ رَبِّكَ خَيْرٌ مِّمَّا يَجْمَعُونَ
Transliteration ahum yaqsimūna raḥmata rabbika naḥnu qasamnā baynahum maʿīshatahum fī l-ḥayati l-dun'yā warafaʿnā baʿḍahum fawqa baʿḍin darajātin liyattakhidha baʿḍuhum baʿḍan sukh'riyyan waraḥmatu rabbika khayrun mimmā yajmaʿūna
Yoruba Ṣé àwọn ni wọn máa pín ìkẹ́ Olúwa rẹ ni? Àwa l’A pín n̄ǹkan ìṣẹ̀mí wọn fún wọn nínú ìgbésí ayé. A sì fi àwọn ipò gíga gbé apá kan wọn ga ju apá kan lọ nítorí kí apá kan wọn lè máa ṣiṣẹ́ fún apá kan. Ìkẹ́ Olúwa rẹ sì lóore jùlọ sí ohun tí wọ́n ń kó jọ.
Verse 33
وَلَوْلَآ أَن يَكُونَ ٱلنَّاسُ أُمَّةً وَٰحِدَةً لَّجَعَلْنَا لِمَن يَكْفُرُ بِٱلرَّحْمَـٰنِ لِبُيُوتِهِمْ سُقُفًا مِّن فِضَّةٍ وَمَعَارِجَ عَلَيْهَا يَظْهَرُونَ
Transliteration walawlā an yakūna l-nāsu ummatan wāḥidatan lajaʿalnā liman yakfuru bil-raḥmāni libuyūtihim suqufan min fiḍḍatin wamaʿārija ʿalayhā yaẓharūna
Yoruba Tí kò bá jẹ́ pé àwọn ènìyàn máa di ìjọ kan ṣoṣo (tí gbogbo wọn máa di kèfèrí nítorí ọrọ̀ ayé), A ìbá ṣe àwọn òrùlé àti àwọn àkàbà tí wọn yóò fi máa gùnkè nínú ilé ní fàdákà fún ẹni tó ń ṣàì gbàgbọ́ nínú Àjọkẹ́-ayé.
Verse 34
وَلِبُيُوتِهِمْ أَبْوَٰبًا وَسُرُرًا عَلَيْهَا يَتَّكِـُٔونَ
Transliteration walibuyūtihim abwāban wasururan ʿalayhā yattakiūna
Yoruba (A ìbá tún ṣe) àwọn ẹnu ọ̀nà ilé wọn àti àwọn ibùsùn tí wọn yóò máa rọ̀gbọ̀kú lé lórí (ní fàdákà)
Verse 35
وَزُخْرُفًا ۚ وَإِن كُلُّ ذَٰلِكَ لَمَّا مَتَـٰعُ ٱلْحَيَوٰةِ ٱلدُّنْيَا ۚ وَٱلْـَٔاخِرَةُ عِندَ رَبِّكَ لِلْمُتَّقِينَ
Transliteration wazukh'rufan wa-in kullu dhālika lammā matāʿu l-ḥayati l-dun'yā wal-ākhiratu ʿinda rabbika lil'muttaqīna
Yoruba àti góòlù.Gbogbo n̄ǹkan wọ̀nyí kò jẹ́ n̄ǹkan kan bí kò ṣe ìgbádùn ìṣẹ̀mí ayé lásán. (Ọgbà Ìdẹ̀ra) Ọ̀run sì wà ní ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ fún àwọn olùbẹ̀rù (Allāhu).
Verse 36
وَمَن يَعْشُ عَن ذِكْرِ ٱلرَّحْمَـٰنِ نُقَيِّضْ لَهُۥ شَيْطَـٰنًا فَهُوَ لَهُۥ قَرِينٌ
Transliteration waman yaʿshu ʿan dhik'ri l-raḥmāni nuqayyiḍ lahu shayṭānan fahuwa lahu qarīnun
Yoruba Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbúnrí kúrò níbi ìrántí Àjọké-ayé, A máa yan èṣù kan fún un. Òun sì ni alábàárìn rẹ̀.
Verse 37
وَإِنَّهُمْ لَيَصُدُّونَهُمْ عَنِ ٱلسَّبِيلِ وَيَحْسَبُونَ أَنَّهُم مُّهْتَدُونَ
Transliteration wa-innahum layaṣuddūnahum ʿani l-sabīli wayaḥsabūna annahum muh'tadūna
Yoruba Dájúdájú àwọn èṣù náà yóò máa ṣẹ́rí wọn kúrò lójú ọ̀nà (ẹ̀sìn Allāhu). Wọn yó sì máa lérò pé dájúdájú àwọn ni olùmọ̀nà.
Verse 38
حَتَّىٰٓ إِذَا جَآءَنَا قَالَ يَـٰلَيْتَ بَيْنِى وَبَيْنَكَ بُعْدَ ٱلْمَشْرِقَيْنِ فَبِئْسَ ٱلْقَرِينُ
Transliteration ḥattā idhā jāanā qāla yālayta baynī wabaynaka buʿ'da l-mashriqayni fabi'sa l-qarīnu
Yoruba Títí di ìgbà tí ó fi máa wá bá Wa, ó sì máa wí pé: “Háà! Kí ó sì jẹ́ pé (ìtakété bí) ìtakété ibùyọ-òòrùn àti ibùwọ̀ rẹ̀ sì wà láààrin èmi àti ìwọ (èṣù alábàárìn yìí, ìbá dára); alábàárìn burúkú sì ni.
Verse 39
وَلَن يَنفَعَكُمُ ٱلْيَوْمَ إِذ ظَّلَمْتُمْ أَنَّكُمْ فِى ٱلْعَذَابِ مُشْتَرِكُونَ
Transliteration walan yanfaʿakumu l-yawma idh ẓalamtum annakum fī l-ʿadhābi mush'tarikūna
Yoruba (Àbámọ̀ yín) kò níí ṣe yín ní àǹfààní ní Òní nígbà tí ẹ ti ṣàbòsí. (Àti pé) dájúdájú ẹ̀yin (àti òrìṣà yín) ni ẹ dìjọ máa kẹ́gbẹ́ nínú ìyà.
Verse 40
أَفَأَنتَ تُسْمِعُ ٱلصُّمَّ أَوْ تَهْدِى ٱلْعُمْىَ وَمَن كَانَ فِى ضَلَـٰلٍ مُّبِينٍ
Transliteration afa-anta tus'miʿu l-ṣuma aw tahdī l-ʿum'ya waman kāna fī ḍalālin mubīnin
Yoruba Ṣé ìwọ l’o máa fún àwọn adití ní ọ̀rọ̀ gbọ́ tàbí o máa fún àwọn afọ́jú ní ìmọ̀nà àti ẹni tí ó wà nínú ìṣìnà pọ́nńbélé?1
Verse 41
فَإِمَّا نَذْهَبَنَّ بِكَ فَإِنَّا مِنْهُم مُّنتَقِمُونَ
Transliteration fa-immā nadhhabanna bika fa-innā min'hum muntaqimūna
Yoruba Nítorí náà, ó ṣeé ṣe kí Á ti mú ọ kúrò (lórí ilẹ̀ ayé ṣíwájú àsìkò ìyà wọn), dájúdájú Àwa yóò gbẹ̀san (ìyà) lára wọn.
Verse 42
أَوْ نُرِيَنَّكَ ٱلَّذِى وَعَدْنَـٰهُمْ فَإِنَّا عَلَيْهِم مُّقْتَدِرُونَ
Transliteration aw nuriyannaka alladhī waʿadnāhum fa-innā ʿalayhim muq'tadirūna
Yoruba Tàbí kí Á fi ohun tí A ṣe ní ìlérí fún wọn hàn ọ́, dájúdájú Àwa jẹ́ Alágbára lórí wọn.
Verse 43
فَٱسْتَمْسِكْ بِٱلَّذِىٓ أُوحِىَ إِلَيْكَ ۖ إِنَّكَ عَلَىٰ صِرَٰطٍ مُّسْتَقِيمٍ
Transliteration fa-is'tamsik bi-alladhī ūḥiya ilayka innaka ʿalā ṣirāṭin mus'taqīmin
Yoruba Nítorí náà, di ohun tí A fi ránṣẹ́ sí ọ mú ṣinṣin. Dájúdájú ìwọ wà lójú ọ̀nà tààrà (’Islām).
Verse 44
وَإِنَّهُۥ لَذِكْرٌ لَّكَ وَلِقَوْمِكَ ۖ وَسَوْفَ تُسْـَٔلُونَ
Transliteration wa-innahu ladhik'run laka waliqawmika wasawfa tus'alūna
Yoruba Dájúdájú al-Ƙur’ān ni tírà ìrántí fún ìwọ àti ìjọ rẹ. Láìpẹ́ wọ́n máa bi yín léèrè (nípa rẹ̀).
Verse 45
وَسْـَٔلْ مَنْ أَرْسَلْنَا مِن قَبْلِكَ مِن رُّسُلِنَآ أَجَعَلْنَا مِن دُونِ ٱلرَّحْمَـٰنِ ءَالِهَةً يُعْبَدُونَ
Transliteration wasal man arsalnā min qablika min rusulinā ajaʿalnā min dūni l-raḥmāni ālihatan yuʿ'badūna
Yoruba Bèèrè wò lọ́wọ́ àwọn tí A rán níṣẹ́ ṣíwájú rẹ nínú àwọn Òjíṣẹ́ Wa (pé): “Ǹjẹ́ A sọ àwọn kan di ọlọ́hun tí wọn yóò máa jọ́sìn fún lẹ́yìn Àjọkẹ́-ayé bí?”1
Verse 46
وَلَقَدْ أَرْسَلْنَا مُوسَىٰ بِـَٔايَـٰتِنَآ إِلَىٰ فِرْعَوْنَ وَمَلَإِي۟هِۦ فَقَالَ إِنِّى رَسُولُ رَبِّ ٱلْعَـٰلَمِينَ
Transliteration walaqad arsalnā mūsā biāyātinā ilā fir'ʿawna wamala-ihi faqāla innī rasūlu rabbi l-ʿālamīna
Yoruba A kúkú fi àwọn àmì Wa rán (Ànábì) Mūsā níṣẹ́ sí Fir‘aon àti àwọn ìjòyè rẹ̀. Ó sì sọ pé: “Dájúdájú èmi ni Òjíṣẹ́ Olúwa gbogbo ẹ̀dá.”
Verse 47
فَلَمَّا جَآءَهُم بِـَٔايَـٰتِنَآ إِذَا هُم مِّنْهَا يَضْحَكُونَ
Transliteration falammā jāahum biāyātinā idhā hum min'hā yaḍḥakūna
Yoruba Ṣùgbọ́n nígbà tí ó mú àwọn àmì Wa wá bá wọn, ńṣe ni wọ́n ń fi àwọn àmì náà rẹ́rìn-ín nígbà náà.
Verse 48
وَمَا نُرِيهِم مِّنْ ءَايَةٍ إِلَّا هِىَ أَكْبَرُ مِنْ أُخْتِهَا ۖ وَأَخَذْنَـٰهُم بِٱلْعَذَابِ لَعَلَّهُمْ يَرْجِعُونَ
Transliteration wamā nurīhim min āyatin illā hiya akbaru min ukh'tihā wa-akhadhnāhum bil-ʿadhābi laʿallahum yarjiʿūna
Yoruba A kò níí fi àmì kan hàn wọ́n àyàfi kí ó tóbi ju irú rẹ̀ (tó ṣíwájú). A sì fi ìyà jẹ wọ́n nítorí kí wọ́n lè ṣẹ́rí padà (síbi òdodo).
Verse 49
وَقَالُوا۟ يَـٰٓأَيُّهَ ٱلسَّاحِرُ ٱدْعُ لَنَا رَبَّكَ بِمَا عَهِدَ عِندَكَ إِنَّنَا لَمُهْتَدُونَ
Transliteration waqālū yāayyuha l-sāḥiru ud'ʿu lanā rabbaka bimā ʿahida ʿindaka innanā lamuh'tadūna
Yoruba Wọ́n sì wí pé: “Ìwọ òpìdán, pe Olúwa rẹ fún wa nítorí àdéhùn tí Ó ṣe pẹ̀lú rẹ. Dájúdájú àwa máa tẹ̀lé ìmọ̀nà Rẹ̀.”
Verse 50
فَلَمَّا كَشَفْنَا عَنْهُمُ ٱلْعَذَابَ إِذَا هُمْ يَنكُثُونَ
Transliteration falammā kashafnā ʿanhumu l-ʿadhāba idhā hum yankuthūna
Yoruba Ṣùgbọ́n nígbà tí A bá mú ìyà kúrò fún wọn, nígbà náà ni wọ́n tún ń yẹ àdéhùn.
Verse 51
وَنَادَىٰ فِرْعَوْنُ فِى قَوْمِهِۦ قَالَ يَـٰقَوْمِ أَلَيْسَ لِى مُلْكُ مِصْرَ وَهَـٰذِهِ ٱلْأَنْهَـٰرُ تَجْرِى مِن تَحْتِىٓ ۖ أَفَلَا تُبْصِرُونَ
Transliteration wanādā fir'ʿawnu fī qawmihi qāla yāqawmi alaysa lī mul'ku miṣ'ra wahādhihi l-anhāru tajrī min taḥtī afalā tub'ṣirūna
Yoruba Fir‘aon sì pèpè láààrin àwọn ènìyàn rẹ̀, ó wí pé: “Ẹ̀yin ènìyàn mi, ṣé tèmi kọ́ ni ìjọba Misrọ àti àwọn odò wọ̀nyí tó ń ṣàn nísàlẹ̀ (ọ̀dọ̀) mi? Ṣé ẹ kò ríran ni?
Verse 52
أَمْ أَنَا۠ خَيْرٌ مِّنْ هَـٰذَا ٱلَّذِى هُوَ مَهِينٌ وَلَا يَكَادُ يُبِينُ
Transliteration am anā khayrun min hādhā alladhī huwa mahīnun walā yakādu yubīnu
Yoruba Tàbí ṣé èmi kò lóore ju èyí tí ó jẹ́ ọ̀lẹ ẹni yẹpẹrẹ, tí ó fẹ́ẹ̀ má lè dá ọ̀rọ̀ sọ yanjú?
Verse 53
فَلَوْلَآ أُلْقِىَ عَلَيْهِ أَسْوِرَةٌ مِّن ذَهَبٍ أَوْ جَآءَ مَعَهُ ٱلْمَلَـٰٓئِكَةُ مُقْتَرِنِينَ
Transliteration falawlā ul'qiya ʿalayhi aswiratun min dhahabin aw jāa maʿahu l-malāikatu muq'tarinīna
Yoruba Kí ni kò jẹ́ kí wọ́n fún un ní àwọn ẹ̀gbà-ọwọ́ góòlù tàbí (kí ni kò jẹ́ kí) àwọn mọlāika wá pẹ̀lú rẹ̀, kí wọ́n jẹ́ alábàárìn (tí wọn yóò máa jẹ́rìí rẹ̀)?”
Verse 54
فَٱسْتَخَفَّ قَوْمَهُۥ فَأَطَاعُوهُ ۚ إِنَّهُمْ كَانُوا۟ قَوْمًا فَـٰسِقِينَ
Transliteration fa-is'takhaffa qawmahu fa-aṭāʿūhu innahum kānū qawman fāsiqīna
Yoruba Nítorí náà, ó sọ àwọn ènìyàn rẹ̀ di òpè. Wọ́n sì tẹ̀lé e. Dájúdájú wọ́n jẹ́ ìjọ òbìlẹ̀jẹ́.
Verse 55
فَلَمَّآ ءَاسَفُونَا ٱنتَقَمْنَا مِنْهُمْ فَأَغْرَقْنَـٰهُمْ أَجْمَعِينَ
Transliteration falammā āsafūnā intaqamnā min'hum fa-aghraqnāhum ajmaʿīna
Yoruba Nígbà tí wọ́n wá ìbínú Wa, A gba ẹ̀san (ìyà) lára wọn. Nítorí náà, A tẹ gbogbo wọn rì (sínú agbami odò).
Verse 56
فَجَعَلْنَـٰهُمْ سَلَفًا وَمَثَلًا لِّلْـَٔاخِرِينَ
Transliteration fajaʿalnāhum salafan wamathalan lil'ākhirīna
Yoruba A sì ṣe wọ́n ní ìjọ aṣíwájú (nínú ìparun) àti àpẹ̀ẹrẹ (fèyíkọ́gbọ́n) fún àwọn ẹni ìkẹ́yìn.
Verse 57
۞ وَلَمَّا ضُرِبَ ٱبْنُ مَرْيَمَ مَثَلًا إِذَا قَوْمُكَ مِنْهُ يَصِدُّونَ
Transliteration walammā ḍuriba ub'nu maryama mathalan idhā qawmuka min'hu yaṣiddūna
Yoruba Nígbà tí àwọn ọ̀ṣẹbọ fi ọmọ Mọryam ṣe àpẹ̀ẹrẹ (fún òrìṣà wọn), nígbà náà ni àwọn ènìyàn rẹ bá ń fi (àpẹ̀ẹrẹ náà) rẹ́rìn-ín.
Verse 58
وَقَالُوٓا۟ ءَأَـٰلِهَتُنَا خَيْرٌ أَمْ هُوَ ۚ مَا ضَرَبُوهُ لَكَ إِلَّا جَدَلًۢا ۚ بَلْ هُمْ قَوْمٌ خَصِمُونَ
Transliteration waqālū aālihatunā khayrun am huwa mā ḍarabūhu laka illā jadalan bal hum qawmun khaṣimūna
Yoruba Wọ́n sì wí pé: “Ṣé àwọn òrìṣà wa l’ó lóore jùlọ ni tàbí òun? Wọn kò wulẹ̀ fi ṣàpẹ̀ẹrẹ fún ọ bí kò ṣe (fún) àtakò. Àní sẹ́, ìjọ oníyànjíjà ni wọ́n.
Verse 59
إِنْ هُوَ إِلَّا عَبْدٌ أَنْعَمْنَا عَلَيْهِ وَجَعَلْنَـٰهُ مَثَلًا لِّبَنِىٓ إِسْرَٰٓءِيلَ
Transliteration in huwa illā ʿabdun anʿamnā ʿalayhi wajaʿalnāhu mathalan libanī is'rāīla
Yoruba Kí ni òun bí kò ṣe ẹrúsìn kan tí A ṣe ìdẹ̀ra fún. A sì ṣe é ní àpẹ̀ẹrẹ rere fún àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl.1
Verse 60
وَلَوْ نَشَآءُ لَجَعَلْنَا مِنكُم مَّلَـٰٓئِكَةً فِى ٱلْأَرْضِ يَخْلُفُونَ
Transliteration walaw nashāu lajaʿalnā minkum malāikatan fī l-arḍi yakhlufūna
Yoruba Tí ó bá jẹ́ pé A bá fẹ́, A ìbá máa fi àwọn mọlāika rọ́pò yín lórí ilẹ̀.
Verse 61
وَإِنَّهُۥ لَعِلْمٌ لِّلسَّاعَةِ فَلَا تَمْتَرُنَّ بِهَا وَٱتَّبِعُونِ ۚ هَـٰذَا صِرَٰطٌ مُّسْتَقِيمٌ
Transliteration wa-innahu laʿil'mun lilssāʿati falā tamtarunna bihā wa-ittabiʿūni hādhā ṣirāṭun mus'taqīmun
Yoruba Dájúdájú òun ni ìmọ̀ (tàbí àmì fún ìsúnmọ́) Àkókò náà. Nítorí náà, ẹ kò gbọdọ̀ ṣeyèméjì lórí rẹ̀. Kí ẹ sì tẹ̀lé mi. Èyí ni ọ̀nà tààrà.1
Verse 62
وَلَا يَصُدَّنَّكُمُ ٱلشَّيْطَـٰنُ ۖ إِنَّهُۥ لَكُمْ عَدُوٌّ مُّبِينٌ
Transliteration walā yaṣuddannakumu l-shayṭānu innahu lakum ʿaduwwun mubīnun
Yoruba Ẹ má ṣe jẹ́ kí Èṣù ṣẹ yín lórí (kúrò lójú ọ̀nà tààrà náà); dájúdájú òun ni ọ̀tá pọ́nńbélé fún yín.
Verse 63
وَلَمَّا جَآءَ عِيسَىٰ بِٱلْبَيِّنَـٰتِ قَالَ قَدْ جِئْتُكُم بِٱلْحِكْمَةِ وَلِأُبَيِّنَ لَكُم بَعْضَ ٱلَّذِى تَخْتَلِفُونَ فِيهِ ۖ فَٱتَّقُوا۟ ٱللَّهَ وَأَطِيعُونِ
Transliteration walammā jāa ʿīsā bil-bayināti qāla qad ji'tukum bil-ḥik'mati wali-ubayyina lakum baʿḍa alladhī takhtalifūna fīhi fa-ittaqū l-laha wa-aṭīʿūni
Yoruba Nígbà tí (Ànábì) ‘Īsā dé pẹ̀lú àwọn ẹ̀rí tó yanjú, ó sọ pé: “Dájúdájú mo dé wá ba yín pẹ̀lú ọgbọ́n ìjìnlẹ̀. (Mo sì dé) nítorí kí n̄g lè ṣe àlàyé apá kan èyí tí ẹ̀ ń yapa-ẹnu lórí rẹ̀ fún yín. Nítorí náà, ẹ bẹ̀rù Allāhu, kí ẹ sì tẹ̀lé mi.
Verse 64
إِنَّ ٱللَّهَ هُوَ رَبِّى وَرَبُّكُمْ فَٱعْبُدُوهُ ۚ هَـٰذَا صِرَٰطٌ مُّسْتَقِيمٌ
Transliteration inna l-laha huwa rabbī warabbukum fa-uʿ'budūhu hādhā ṣirāṭun mus'taqīmun
Yoruba Dájúdájú Allāhu ni Olúwa mi àti Olúwa yín. Nítorí náà, ẹ jọ́sìn fún Un. Èyí ni ọ̀nà tààrà.”
Verse 65
فَٱخْتَلَفَ ٱلْأَحْزَابُ مِنۢ بَيْنِهِمْ ۖ فَوَيْلٌ لِّلَّذِينَ ظَلَمُوا۟ مِنْ عَذَابِ يَوْمٍ أَلِيمٍ
Transliteration fa-ikh'talafa l-aḥzābu min baynihim fawaylun lilladhīna ẓalamū min ʿadhābi yawmin alīmin
Yoruba Àwọn ìjọ (rẹ̀) sì yapa (ẹ̀sìn ’Islām) láààrin ara wọn. Nítorí náà, ègbé ni fún àwọn tó ṣàbòsí ní ọjọ́ ìyà ẹlẹ́ta-eléro.
Verse 66
هَلْ يَنظُرُونَ إِلَّا ٱلسَّاعَةَ أَن تَأْتِيَهُم بَغْتَةً وَهُمْ لَا يَشْعُرُونَ
Transliteration hal yanẓurūna illā l-sāʿata an tatiyahum baghtatan wahum lā yashʿurūna
Yoruba Ṣé wọ́n ń retí kiní kan bí kò ṣe Àkókò náà; tí ó máa dé bá wọn ní òjijì; wọn kò sì níí fura?
Verse 67
ٱلْأَخِلَّآءُ يَوْمَئِذٍۭ بَعْضُهُمْ لِبَعْضٍ عَدُوٌّ إِلَّا ٱلْمُتَّقِينَ
Transliteration al-akhilāu yawma-idhin baʿḍuhum libaʿḍin ʿaduwwun illā l-mutaqīna
Yoruba Àwọn ọ̀rẹ́ àyò ní ọjọ́ yẹn, apá kan wọn yóò jẹ́ ọ̀tá fún apá kan àyàfi àwọn olùbẹ̀rù (Allāhu).
Verse 68
يَـٰعِبَادِ لَا خَوْفٌ عَلَيْكُمُ ٱلْيَوْمَ وَلَآ أَنتُمْ تَحْزَنُونَ
Transliteration yāʿibādi lā khawfun ʿalaykumu l-yawma walā antum taḥzanūna
Yoruba Ẹ̀yin ẹrúsìn Mi, kò sí ìbẹ̀rù fún yín ní òní. Ẹ̀yin kò sì níí banújẹ́.
Verse 69
ٱلَّذِينَ ءَامَنُوا۟ بِـَٔايَـٰتِنَا وَكَانُوا۟ مُسْلِمِينَ
Transliteration alladhīna āmanū biāyātinā wakānū mus'limīna
Yoruba (Àwọn ni) àwọn tó gbàgbọ́ nínú àwọn āyah Wa, tí wọ́n sì jẹ́ mùsùlùmí (olùjuwọ́-jusẹ̀ sílẹ̀ fún Allāhu).
Verse 70
ٱدْخُلُوا۟ ٱلْجَنَّةَ أَنتُمْ وَأَزْوَٰجُكُمْ تُحْبَرُونَ
Transliteration ud'khulū l-janata antum wa-azwājukum tuḥ'barūna
Yoruba Ẹ wọ inú Ọgbà Ìdẹ̀ra, ẹ̀yin àti àwọn ìyàwó yín; kí wọ́n máa dun yín nínú.
Verse 71
يُطَافُ عَلَيْهِم بِصِحَافٍ مِّن ذَهَبٍ وَأَكْوَابٍ ۖ وَفِيهَا مَا تَشْتَهِيهِ ٱلْأَنفُسُ وَتَلَذُّ ٱلْأَعْيُنُ ۖ وَأَنتُمْ فِيهَا خَـٰلِدُونَ
Transliteration yuṭāfu ʿalayhim biṣiḥāfin min dhahabin wa-akwābin wafīhā mā tashtahīhi l-anfusu wataladhu l-aʿyunu wa-antum fīhā khālidūna
Yoruba Wọn yóò máa gbé àwọn àwo góòlù àti àwọn ife ìmumi káà kiri ọ̀dọ̀ wọn. Ohun tí ẹ̀mí ń fẹ́ àti (ohun tí) ojú yóò máa dúnnú sí wà nínú rẹ̀. Olùṣegbére sì ni yín nínú rẹ̀.
Verse 72
وَتِلْكَ ٱلْجَنَّةُ ٱلَّتِىٓ أُورِثْتُمُوهَا بِمَا كُنتُمْ تَعْمَلُونَ
Transliteration watil'ka l-janatu allatī ūrith'tumūhā bimā kuntum taʿmalūna
Yoruba Ìyẹn ni Ọgbà Ìdẹ̀ra tí A jogún rẹ̀ fún yín nítorí ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.
Verse 73
لَكُمْ فِيهَا فَـٰكِهَةٌ كَثِيرَةٌ مِّنْهَا تَأْكُلُونَ
Transliteration lakum fīhā fākihatun kathīratun min'hā takulūna
Yoruba Èso púpọ̀ wà fún yín nínú rẹ̀. Ẹ̀yin yó sì máa jẹ nínú rẹ̀.
Verse 74
إِنَّ ٱلْمُجْرِمِينَ فِى عَذَابِ جَهَنَّمَ خَـٰلِدُونَ
Transliteration inna l-muj'rimīna fī ʿadhābi jahannama khālidūna
Yoruba Dájúdájú àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ni olùṣegbére nínú ìyà iná Jahanamọ.
Verse 75
لَا يُفَتَّرُ عَنْهُمْ وَهُمْ فِيهِ مُبْلِسُونَ
Transliteration lā yufattaru ʿanhum wahum fīhi mub'lisūna
Yoruba A kò níí gbé e fúyẹ́ fún wọn. Wọn yó sì sọ̀rètí nù nínú Iná.
Verse 76
وَمَا ظَلَمْنَـٰهُمْ وَلَـٰكِن كَانُوا۟ هُمُ ٱلظَّـٰلِمِينَ
Transliteration wamā ẓalamnāhum walākin kānū humu l-ẓālimīna
Yoruba A kò ṣàbòsí sí wọn, ṣùgbọ́n àwọn ni wọ́n jẹ́ alábòsí.
Verse 77
وَنَادَوْا۟ يَـٰمَـٰلِكُ لِيَقْضِ عَلَيْنَا رَبُّكَ ۖ قَالَ إِنَّكُم مَّـٰكِثُونَ
Transliteration wanādaw yāmāliku liyaqḍi ʿalaynā rabbuka qāla innakum mākithūna
Yoruba Wọn yóò pe (mọlāika kan) pé: “Mọ̄lik (ẹ̀ṣọ́ Iná), jẹ́ kí Olúwa rẹ pa wá ráúráú.” (Mọ̄lik) yóò sọ pé: “Dájúdájú ẹ̀yin yóò máa gbé inú rẹ̀ ni.”
Verse 78
لَقَدْ جِئْنَـٰكُم بِٱلْحَقِّ وَلَـٰكِنَّ أَكْثَرَكُمْ لِلْحَقِّ كَـٰرِهُونَ
Transliteration laqad ji'nākum bil-ḥaqi walākinna aktharakum lil'ḥaqqi kārihūna
Yoruba Dájúdájú A ti mú òdodo wá ba yín, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ yin kórira òdodo.
Verse 79
أَمْ أَبْرَمُوٓا۟ أَمْرًا فَإِنَّا مُبْرِمُونَ
Transliteration am abramū amran fa-innā mub'rimūna
Yoruba Tàbí àwọn (aláìgbàgbọ́) ti pinnu ọ̀rọ̀ kan ni? Dájúdájú Àwa náà ń pinnu ọ̀rọ̀.
Verse 80
أَمْ يَحْسَبُونَ أَنَّا لَا نَسْمَعُ سِرَّهُمْ وَنَجْوَىٰهُم ۚ بَلَىٰ وَرُسُلُنَا لَدَيْهِمْ يَكْتُبُونَ
Transliteration am yaḥsabūna annā lā nasmaʿu sirrahum wanajwāhum balā warusulunā ladayhim yaktubūna
Yoruba Tàbí wọ́n ń lérò pé Àwa kò gbọ́ ọ̀rọ̀ àṣírí wọn àti ọ̀rọ̀ ìkọ̀kọ̀ wọn? Bẹ́ẹ̀ ni (À ń gbọ́ ọ); àwọn Òjíṣẹ́ Wa wà ní ọ̀dọ̀ wọn, tí wọ́n ń ṣe àkọsílẹ̀ (ọ̀rọ̀ wọn).
Verse 81
قُلْ إِن كَانَ لِلرَّحْمَـٰنِ وَلَدٌ فَأَنَا۠ أَوَّلُ ٱلْعَـٰبِدِينَ
Transliteration qul in kāna lilrraḥmāni waladun fa-anā awwalu l-ʿābidīna
Yoruba Sọ pé: “Kò sí ọmọ kan fún Àjọké ayé. Nítorí náà, èmi ni ẹni àkọ́kọ́ nínú àwọn olùjọ́sìn (fún Allāhu ní àsìkò tèmi).1
Verse 82
سُبْحَـٰنَ رَبِّ ٱلسَّمَـٰوَٰتِ وَٱلْأَرْضِ رَبِّ ٱلْعَرْشِ عَمَّا يَصِفُونَ
Transliteration sub'ḥāna rabbi l-samāwāti wal-arḍi rabbi l-ʿarshi ʿammā yaṣifūna
Yoruba Mímọ́ ni fún Olúwa àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀, Olúwa Ìtẹ́-ọlá tayọ irọ́ tí wọ́n ń pa (mọ́ Ọn).
Verse 83
فَذَرْهُمْ يَخُوضُوا۟ وَيَلْعَبُوا۟ حَتَّىٰ يُلَـٰقُوا۟ يَوْمَهُمُ ٱلَّذِى يُوعَدُونَ
Transliteration fadharhum yakhūḍū wayalʿabū ḥattā yulāqū yawmahumu alladhī yūʿadūna
Yoruba Nítorí náà, fi wọ́n sílẹ̀ kí wọ́n máa sọ ìsọkúsọ (wọn), kí wọ́n sì máa ṣeré wọn lọ títí wọn yóò fi pàdé ọjọ́ wọn, tí À ń ṣe ní àdéhùn fún wọn.
Verse 84
وَهُوَ ٱلَّذِى فِى ٱلسَّمَآءِ إِلَـٰهٌ وَفِى ٱلْأَرْضِ إِلَـٰهٌ ۚ وَهُوَ ٱلْحَكِيمُ ٱلْعَلِيمُ
Transliteration wahuwa alladhī fī l-samāi ilāhun wafī l-arḍi ilāhun wahuwa l-ḥakīmu l-ʿalīmu
Yoruba (Allāhu) Òun ni Ọlọ́hun tí wọ́n ń jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo nínú sánmọ̀. Òun náà sì ni Ọlọ́hun tí wọ́n gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo lórí ilẹ̀. Òun ni Ọlọ́gbọ́n, Onímọ̀.
Verse 85
وَتَبَارَكَ ٱلَّذِى لَهُۥ مُلْكُ ٱلسَّمَـٰوَٰتِ وَٱلْأَرْضِ وَمَا بَيْنَهُمَا وَعِندَهُۥ عِلْمُ ٱلسَّاعَةِ وَإِلَيْهِ تُرْجَعُونَ
Transliteration watabāraka alladhī lahu mul'ku l-samāwāti wal-arḍi wamā baynahumā waʿindahu ʿil'mu l-sāʿati wa-ilayhi tur'jaʿūna
Yoruba Ìbùkún ni fún Ẹni tí Ó ni ìjọba àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ àti ohunkóhun tó wà láààrin méjèèjì. Ọ̀dọ̀ Rẹ̀ sì ni ìmọ̀ Àkókò náà wà. Ọ̀dọ̀ Rẹ̀ sì ni wọ́n máa da yín padà sí.
Verse 86
وَلَا يَمْلِكُ ٱلَّذِينَ يَدْعُونَ مِن دُونِهِ ٱلشَّفَـٰعَةَ إِلَّا مَن شَهِدَ بِٱلْحَقِّ وَهُمْ يَعْلَمُونَ
Transliteration walā yamliku alladhīna yadʿūna min dūnihi l-shafāʿata illā man shahida bil-ḥaqi wahum yaʿlamūna
Yoruba Àwọn tí wọ́n ń pè lẹ́yìn Rẹ̀, wọn kò ní ìkápá ìṣìpẹ̀ àyàfi ẹni tí ó bá jẹ́rìí sí òdodo (kalmọtuṣ-ṣahaadah), tí wọ́n sì nímọ̀ (rẹ̀).1
Verse 87
وَلَئِن سَأَلْتَهُم مَّنْ خَلَقَهُمْ لَيَقُولُنَّ ٱللَّهُ ۖ فَأَنَّىٰ يُؤْفَكُونَ
Transliteration wala-in sa-altahum man khalaqahum layaqūlunna l-lahu fa-annā yu'fakūna
Yoruba Àti pé tí o bá bi wọ́n léèrè pé: “Ta ni Ó dá wọn?”, dájúdájú wọn á wí pé: “Allāhu ni.” Nítorí náà, báwo ni wọ́n ṣe ń ṣẹ́rí wọn kúrò níbi òdodo?
Verse 88
وَقِيلِهِۦ يَـٰرَبِّ إِنَّ هَـٰٓؤُلَآءِ قَوْمٌ لَّا يُؤْمِنُونَ
Transliteration waqīlihi yārabbi inna hāulāi qawmun lā yu'minūna
Yoruba Ọ̀rọ̀ (tí Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - ń sọ fún Allāhu ni pé): “Olúwa Mi, dájúdájú àwọn wọ̀nyí ni ìjọ tí kò gbàgbọ́.”
Verse 89
فَٱصْفَحْ عَنْهُمْ وَقُلْ سَلَـٰمٌ ۚ فَسَوْفَ يَعْلَمُونَ
Transliteration fa-iṣ'faḥ ʿanhum waqul salāmun fasawfa yaʿlamūna
Yoruba Nítorí náà, ṣàmójú kúrò fún wọn, kí ó sì sọ pé: “Àlàáfíà!” Láìpẹ́ wọ́n máa mọ̀.
Read Surah Az-Zukhruf in another language
- English (word by word)
- Albanian
- Amazigh
- Amharic
- Assamese
- Azerbaijani
- Bambara
- Bangla
- Bosnian
- Bulgarian
- Chechen
- Chinese
- Czech
- Dari
- Dhivehi
- Dutch
- Finnish
- French
- German
- Gujarati
- Hausa
- Hebrew
- Hindi
- Indonesian
- Italian
- Japanese
- Kannada
- Kazakh
- Khmer
- Kinyarwanda
- Korean
- Kurdish
- Luganda
- Malay
- Malayalam
- Maranao
- Marathi
- Nepali
- Norwegian
- Oromo
- Pashto
- Persian
- Polish
- Portuguese
- Romanian
- Russian
- Sindhi
- Sinhala
- Somali
- Spanish
- Swahili
- Swedish
- Tagalog
- Tajik
- Tamil
- Tatar
- Telugu
- Thai
- Turkish
- Ukrainian
- Urdu
- Uyghur
- Uzbek
- Vietnamese
- Yao
All 114 surahs in Yoruba: the Qur’an in Yoruba.
Yoruba translation: Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni, from Quran.com. Transliteration: Quran.com. Recitation: Mishary Alafasy, from EveryAyah.com. MyDugsi is a learning aid, not a replacement for a qualified teacher.