MyDugsiStart learning

Surah Ash-Shuraa in Yoruba: translation and audio

Surah 42 · الشورى · The Consultation · 53 verses

Surah Ash-Shuraa verse by verse: the Arabic with a recitation you can repeat, the transliteration, and the Yoruba translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni. For the meaning of every word, see Surah Ash-Shuraa word by word in English.

Verse 1

حمٓ

Transliteration hha-meem

Yoruba Hā mīm.

Verse 2

عٓسٓقٓ

Transliteration ain-seen-qaf

Yoruba ‘Aēn sīn ƙọ̄f. (Allāhu ló mọ ohun tí Ó gbàlérò pẹ̀lú àwọn háràfí náà.)1

Verse 3

كَذَٰلِكَ يُوحِىٓ إِلَيْكَ وَإِلَى ٱلَّذِينَ مِن قَبْلِكَ ٱللَّهُ ٱلْعَزِيزُ ٱلْحَكِيمُ

Transliteration kadhālika yūḥī ilayka wa-ilā alladhīna min qablika l-lahu l-ʿazīzu l-ḥakīmu

Yoruba Báyẹn ni Allāhu, Alágbára, Ọlọ́gbọ́n ṣe ń fi ìmísí ránṣẹ́ sí ìwọ àti àwọn tó ṣíwájú rẹ.1

Verse 4

لَهُۥ مَا فِى ٱلسَّمَـٰوَٰتِ وَمَا فِى ٱلْأَرْضِ ۖ وَهُوَ ٱلْعَلِىُّ ٱلْعَظِيمُ

Transliteration lahu mā fī l-samāwāti wamā fī l-arḍi wahuwa l-ʿaliyu l-ʿaẓīmu

Yoruba TiRẹ̀ ni ohunkóhun tó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ohunkóhun tó wà nínú ilẹ̀. Ó ga, Ó tóbi.

Verse 5

تَكَادُ ٱلسَّمَـٰوَٰتُ يَتَفَطَّرْنَ مِن فَوْقِهِنَّ ۚ وَٱلْمَلَـٰٓئِكَةُ يُسَبِّحُونَ بِحَمْدِ رَبِّهِمْ وَيَسْتَغْفِرُونَ لِمَن فِى ٱلْأَرْضِ ۗ أَلَآ إِنَّ ٱللَّهَ هُوَ ٱلْغَفُورُ ٱلرَّحِيمُ

Transliteration takādu l-samāwātu yatafaṭṭarna min fawqihinna wal-malāikatu yusabbiḥūna biḥamdi rabbihim wayastaghfirūna liman fī l-arḍi alā inna l-laha huwa l-ghafūru l-raḥīmu

Yoruba Sánmọ̀ fẹ́ẹ̀ fàya láti òkè wọn (nípa títóbi Allāhu). Àwọn mọlāika sì ń ṣe àfọ̀mọ́ pẹ̀lú ẹyìn fún Olúwa wọn. Wọ́n sì ńtọrọ àforíjìn fún àwọn tó wà lórí ilẹ̀. Gbọ́, dájúdájú Allāhu, Òun ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.

Verse 6

وَٱلَّذِينَ ٱتَّخَذُوا۟ مِن دُونِهِۦٓ أَوْلِيَآءَ ٱللَّهُ حَفِيظٌ عَلَيْهِمْ وَمَآ أَنتَ عَلَيْهِم بِوَكِيلٍ

Transliteration wa-alladhīna ittakhadhū min dūnihi awliyāa l-lahu ḥafīẓun ʿalayhim wamā anta ʿalayhim biwakīlin

Yoruba Àwọn tó mú àwọn alátìlẹ́yìn kan lẹ́yìn Rẹ̀, Allāhu sì ni Aláàbò lórí wọn. Ìwọ sì kọ́ ni olùṣọ́ lórí wọn.

Verse 7

وَكَذَٰلِكَ أَوْحَيْنَآ إِلَيْكَ قُرْءَانًا عَرَبِيًّا لِّتُنذِرَ أُمَّ ٱلْقُرَىٰ وَمَنْ حَوْلَهَا وَتُنذِرَ يَوْمَ ٱلْجَمْعِ لَا رَيْبَ فِيهِ ۚ فَرِيقٌ فِى ٱلْجَنَّةِ وَفَرِيقٌ فِى ٱلسَّعِيرِ

Transliteration wakadhālika awḥaynā ilayka qur'ānan ʿarabiyyan litundhira umma l-qurā waman ḥawlahā watundhira yawma l-jamʿi lā rayba fīhi farīqun fī l-janati wafarīqun fī l-saʿīri

Yoruba Báyẹn ni A ṣe fi al-Ƙur’ān ránṣẹ́ sí ọ ní èdè Lárúbáwá nítorí kí o lè fi ṣe ìkìlọ̀ fún ’Ummul-Ƙurọ̄ (ìyẹn, ará ìlú Mọkkah) àti ẹnikẹ́ni tí ó bá wà ní àyíká rẹ̀ (ìyẹn, ará ìlú yòókù), àti nítorí kí o lè fi ṣe ìkìlọ̀ nípa Ọjọ́ Àkójọ, tí kò sí iyèméjì nínú rẹ̀. Ìjọ kan yóò wà nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra. Ìjọ kan yó sì wà nínú Iná tó ń jo.

Verse 8

وَلَوْ شَآءَ ٱللَّهُ لَجَعَلَهُمْ أُمَّةً وَٰحِدَةً وَلَـٰكِن يُدْخِلُ مَن يَشَآءُ فِى رَحْمَتِهِۦ ۚ وَٱلظَّـٰلِمُونَ مَا لَهُم مِّن وَلِىٍّ وَلَا نَصِيرٍ

Transliteration walaw shāa l-lahu lajaʿalahum ummatan wāḥidatan walākin yud'khilu man yashāu fī raḥmatihi wal-ẓālimūna mā lahum min waliyyin walā naṣīrin

Yoruba Tí ó bá jẹ́ pé Allāhu bá fẹ́, ìbá ṣe wọ́n ní ìjọ ẹlẹ́sìn ẹyọ kan. Ṣùgbọ́n Ó ń fi ẹni tí Ó bá fẹ́ sínú ìkẹ́ Rẹ̀. Àwọn alábòsí, kò sì níí sí aláàbò àti alárànṣe kan fún wọn.

Verse 9

أَمِ ٱتَّخَذُوا۟ مِن دُونِهِۦٓ أَوْلِيَآءَ ۖ فَٱللَّهُ هُوَ ٱلْوَلِىُّ وَهُوَ يُحْىِ ٱلْمَوْتَىٰ وَهُوَ عَلَىٰ كُلِّ شَىْءٍ قَدِيرٌ

Transliteration ami ittakhadhū min dūnihi awliyāa fal-lahu huwa l-waliyu wahuwa yuḥ'yī l-mawtā wahuwa ʿalā kulli shayin qadīrun

Yoruba Ṣé wọ́n mú àwọn aláàbò kan lẹ́yìn Rẹ̀ ni? Allāhu, Òun sì ni Aláàbò. Òun l’Ó ń sọ àwọn òkú di alààyè. Òun sì ni Alágbára lórí gbogbo n̄ǹkan.

Verse 10

وَمَا ٱخْتَلَفْتُمْ فِيهِ مِن شَىْءٍ فَحُكْمُهُۥٓ إِلَى ٱللَّهِ ۚ ذَٰلِكُمُ ٱللَّهُ رَبِّى عَلَيْهِ تَوَكَّلْتُ وَإِلَيْهِ أُنِيبُ

Transliteration wamā ikh'talaftum fīhi min shayin faḥuk'muhu ilā l-lahi dhālikumu l-lahu rabbī ʿalayhi tawakkaltu wa-ilayhi unību

Yoruba Ohunkóhun tí ẹ bá yapa-ẹnu lórí rẹ̀, ìdájọ́ rẹ̀ di ọ̀dọ̀ Allāhu. Ìyẹn ni Allāhu, Olúwa mi. Òun ni mo gbáralé. Ọ̀dọ̀ Rẹ̀ sì ni mo máa ṣẹ́rí padà sí (ní ti ìronúpìwàdà). 1

Verse 11

فَاطِرُ ٱلسَّمَـٰوَٰتِ وَٱلْأَرْضِ ۚ جَعَلَ لَكُم مِّنْ أَنفُسِكُمْ أَزْوَٰجًا وَمِنَ ٱلْأَنْعَـٰمِ أَزْوَٰجًا ۖ يَذْرَؤُكُمْ فِيهِ ۚ لَيْسَ كَمِثْلِهِۦ شَىْءٌ ۖ وَهُوَ ٱلسَّمِيعُ ٱلْبَصِيرُ

Transliteration fāṭiru l-samāwāti wal-arḍi jaʿala lakum min anfusikum azwājan wamina l-anʿāmi azwājan yadhra-ukum fīhi laysa kamith'lihi shayon wahuwa l-samīʿu l-baṣīru

Yoruba (Òun ni) Olùpilẹ̀dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Ó ṣẹ̀dá àwọn obìnrin fún yín láti ara yín. Ó tún ṣẹ̀dá àwọn abo ẹran-ọ̀sìn láti ara àwọn akọ ẹran-ọ̀sìn. Ó ń mu yín pọ̀ sí i (nípa ìṣẹ̀dá yín ní akọ-abo). Kò sí kiní kan bí irú Rẹ̀. Òun sì ni Olùgbọ́, Olùríran.

Verse 12

لَهُۥ مَقَالِيدُ ٱلسَّمَـٰوَٰتِ وَٱلْأَرْضِ ۖ يَبْسُطُ ٱلرِّزْقَ لِمَن يَشَآءُ وَيَقْدِرُ ۚ إِنَّهُۥ بِكُلِّ شَىْءٍ عَلِيمٌ

Transliteration lahu maqālīdu l-samāwāti wal-arḍi yabsuṭu l-riz'qa liman yashāu wayaqdiru innahu bikulli shayin ʿalīmun

Yoruba TiRẹ̀ ni àwọn kọ́kọ́rọ́ ilé ọ̀rọ̀ àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Ó ń tẹ́ arísìkí sílẹ̀ fún ẹni tí Ó bá fẹ́. Ó sì ń díwọ̀n rẹ̀ (fún ẹlòmíìràn). Dájúdájú Òun ni Onímọ̀ nípa gbogbo n̄ǹkan.

Verse 13

۞ شَرَعَ لَكُم مِّنَ ٱلدِّينِ مَا وَصَّىٰ بِهِۦ نُوحًا وَٱلَّذِىٓ أَوْحَيْنَآ إِلَيْكَ وَمَا وَصَّيْنَا بِهِۦٓ إِبْرَٰهِيمَ وَمُوسَىٰ وَعِيسَىٰٓ ۖ أَنْ أَقِيمُوا۟ ٱلدِّينَ وَلَا تَتَفَرَّقُوا۟ فِيهِ ۚ كَبُرَ عَلَى ٱلْمُشْرِكِينَ مَا تَدْعُوهُمْ إِلَيْهِ ۚ ٱللَّهُ يَجْتَبِىٓ إِلَيْهِ مَن يَشَآءُ وَيَهْدِىٓ إِلَيْهِ مَن يُنِيبُ

Transliteration sharaʿa lakum mina l-dīni mā waṣṣā bihi nūḥan wa-alladhī awḥaynā ilayka wamā waṣṣaynā bihi ib'rāhīma wamūsā waʿīsā an aqīmū l-dīna walā tatafarraqū fīhi kabura ʿalā l-mush'rikīna mā tadʿūhum ilayhi l-lahu yajtabī ilayhi man yashāu wayahdī ilayhi man yunību

Yoruba (Allāhu) ṣe ní òfin fún yín nínú ẹ̀sìn (’Islām) ohun tí Ó pa ní àṣẹ fún (Ànábì) Nūh àti èyí tí Ó fi ránṣẹ́ sí ọ, àti ohun tí A pa láṣẹ fún (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm, (Ànábì) Mūsā àti (Ànábì) ‘Īsā pé, kí ẹ gbé ẹ̀sìn náà dúró. Kí ẹ sì má ṣe pín sí ìjọ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ nínú rẹ̀. Wàhálà l’ó jẹ́ fún àwọn ọ̀ṣẹbọ nípa n̄ǹkan tí ò ń pè wọ́n sí (níbi mímú Allāhu ní ọ̀kan ṣoṣo). Allāhu l’Ó ń ṣẹ̀ṣà ẹni tí Ó bá fẹ́ sínú ẹ̀sìn Rẹ̀ (tí ò ń pè wọ́n sí). Ó sì ń fi ọ̀nà mọ ẹni tí ó bá ń ṣẹ́rí padà sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀ (nípasẹ̀ ìronúpìwàdà).

Verse 14

وَمَا تَفَرَّقُوٓا۟ إِلَّا مِنۢ بَعْدِ مَا جَآءَهُمُ ٱلْعِلْمُ بَغْيًۢا بَيْنَهُمْ ۚ وَلَوْلَا كَلِمَةٌ سَبَقَتْ مِن رَّبِّكَ إِلَىٰٓ أَجَلٍ مُّسَمًّى لَّقُضِىَ بَيْنَهُمْ ۚ وَإِنَّ ٱلَّذِينَ أُورِثُوا۟ ٱلْكِتَـٰبَ مِنۢ بَعْدِهِمْ لَفِى شَكٍّ مِّنْهُ مُرِيبٍ

Transliteration wamā tafarraqū illā min baʿdi mā jāahumu l-ʿil'mu baghyan baynahum walawlā kalimatun sabaqat min rabbika ilā ajalin musamman laquḍiya baynahum wa-inna alladhīna ūrithū l-kitāba min baʿdihim lafī shakkin min'hu murībin

Yoruba (Àwọn ọ̀ṣẹbọ) kò sì pín sí ìjọ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ àfi lẹ́yìn tí ìmọ̀ (’Islām) dé bá wọn ní ti ìlara láààrin ara wọn (sí àwọn Ànábì - kí ọlà Allāhu máa bá wọn -). Tí kò bá jẹ́ pé ọ̀rọ̀ kan tí ṣíwájú lọ́dọ̀ Olúwa rẹ (pé Òun yóò lọ́ wọn lára) títí di gbèdéke àkókò kan ni, Wọn ìbá ti dájọ́ láààrin wọn. Dájúdájú àwọn tí A jogún Tírà fún lẹ́yìn wọn sì tún wà nínú iyèméjì tó gbópọn nípa ’Islām.

Verse 15

فَلِذَٰلِكَ فَٱدْعُ ۖ وَٱسْتَقِمْ كَمَآ أُمِرْتَ ۖ وَلَا تَتَّبِعْ أَهْوَآءَهُمْ ۖ وَقُلْ ءَامَنتُ بِمَآ أَنزَلَ ٱللَّهُ مِن كِتَـٰبٍ ۖ وَأُمِرْتُ لِأَعْدِلَ بَيْنَكُمُ ۖ ٱللَّهُ رَبُّنَا وَرَبُّكُمْ ۖ لَنَآ أَعْمَـٰلُنَا وَلَكُمْ أَعْمَـٰلُكُمْ ۖ لَا حُجَّةَ بَيْنَنَا وَبَيْنَكُمُ ۖ ٱللَّهُ يَجْمَعُ بَيْنَنَا ۖ وَإِلَيْهِ ٱلْمَصِيرُ

Transliteration falidhālika fa-ud'ʿu wa-is'taqim kamā umir'ta walā tattabiʿ ahwāahum waqul āmantu bimā anzala l-lahu min kitābin wa-umir'tu li-aʿdila baynakumu l-lahu rabbunā warabbukum lanā aʿmālunā walakum aʿmālukum lā ḥujjata baynanā wabaynakumu l-lahu yajmaʿu baynanā wa-ilayhi l-maṣīru

Yoruba Nítorí ìyẹn, pèpè (sínú ’Islām), kí o sì dúró ṣinṣin gẹ́gẹ́ bí Wọ́n ṣe pa ọ́ lásẹ. Má sì ṣe tẹ̀lé ìfẹ́-inú wọn. Kí o sì sọ pé: “Mo gbàgbọ́ nínú èyíkéyìí Tírà tí Allāhu sọ̀kalẹ̀. Wọ́n sì pa mí láṣẹ pé kí n̄g ṣe déédé láààrin yín. Allāhu ni Olúwa wa àti Olúwa yín. Tiwa ni àwọn iṣẹ́ wa. Tiyín sì ni àwọn iṣẹ́ yín. Kò sí ìjà láààrin àwa àti ẹ̀yin.Allāhu l’Ó sì máa kó wa jọ papọ̀. Ọ̀dọ̀ Rẹ̀ sì ní àbọ̀ ẹ̀dá.”

Verse 16

وَٱلَّذِينَ يُحَآجُّونَ فِى ٱللَّهِ مِنۢ بَعْدِ مَا ٱسْتُجِيبَ لَهُۥ حُجَّتُهُمْ دَاحِضَةٌ عِندَ رَبِّهِمْ وَعَلَيْهِمْ غَضَبٌ وَلَهُمْ عَذَابٌ شَدِيدٌ

Transliteration wa-alladhīna yuḥājjūna fī l-lahi min baʿdi mā us'tujība lahu ḥujjatuhum dāḥiḍatun ʿinda rabbihim waʿalayhim ghaḍabun walahum ʿadhābun shadīdun

Yoruba Àwọn tó ń bá (Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -) jà nípa (ẹ̀sìn) Allāhu lẹ́yìn ìgbà tí àwọn ènìyàn ti gbà fún un, ẹ̀rí wọn máa wó lọ́dọ̀ Olúwa wọn. Ìbínú ń bẹ lórí wọn. Ìyà líle sì wà fún wọn.

Verse 17

ٱللَّهُ ٱلَّذِىٓ أَنزَلَ ٱلْكِتَـٰبَ بِٱلْحَقِّ وَٱلْمِيزَانَ ۗ وَمَا يُدْرِيكَ لَعَلَّ ٱلسَّاعَةَ قَرِيبٌ

Transliteration al-lahu alladhī anzala l-kitāba bil-ḥaqi wal-mīzāna wamā yud'rīka laʿalla l-sāʿata qarībun

Yoruba Allāhu ni Ẹni tí Ó sọ Tírà (al-Ƙur’ān) àti (òfin) òṣùwọ̀n (déédé) kalẹ̀ pẹ̀lú òdodo.Àti pé kí l’ó máa fi mọ̀ ọ́ pé ó ṣeé ṣe kí Àkókò náà ti súnmọ́!

Verse 18

يَسْتَعْجِلُ بِهَا ٱلَّذِينَ لَا يُؤْمِنُونَ بِهَا ۖ وَٱلَّذِينَ ءَامَنُوا۟ مُشْفِقُونَ مِنْهَا وَيَعْلَمُونَ أَنَّهَا ٱلْحَقُّ ۗ أَلَآ إِنَّ ٱلَّذِينَ يُمَارُونَ فِى ٱلسَّاعَةِ لَفِى ضَلَـٰلٍۭ بَعِيدٍ

Transliteration yastaʿjilu bihā alladhīna lā yu'minūna bihā wa-alladhīna āmanū mush'fiqūna min'hā wayaʿlamūna annahā l-ḥaqu alā inna alladhīna yumārūna fī l-sāʿati lafī ḍalālin baʿīdin

Yoruba Àwọn tí kò ní ìgbàgbọ́ òdodo nínú rẹ̀ ń wá a pẹ̀lú ìkánjú. Àwọn tó sì gbàgbọ́ ní òdodo ń páyà rẹ̀. Wọ́n sì mọ̀ pé dájúdájú òdodo ni. Kíyè sí i, dájúdájú àwọn tó ń jiyàn nípa Àkókò náà ti wà nínú ìṣìnà tó jìnnà.

Verse 19

ٱللَّهُ لَطِيفٌۢ بِعِبَادِهِۦ يَرْزُقُ مَن يَشَآءُ ۖ وَهُوَ ٱلْقَوِىُّ ٱلْعَزِيزُ

Transliteration al-lahu laṭīfun biʿibādihi yarzuqu man yashāu wahuwa l-qawiyu l-ʿazīzu

Yoruba Allāhu ni Aláàánú fún àwọn ẹrúsìn Rẹ̀. Ó ń ṣe arísìkí fún ẹni tí Ó bá fẹ́. Òun sì ni Alágbára, Olùborí.

Verse 20

مَن كَانَ يُرِيدُ حَرْثَ ٱلْـَٔاخِرَةِ نَزِدْ لَهُۥ فِى حَرْثِهِۦ ۖ وَمَن كَانَ يُرِيدُ حَرْثَ ٱلدُّنْيَا نُؤْتِهِۦ مِنْهَا وَمَا لَهُۥ فِى ٱلْـَٔاخِرَةِ مِن نَّصِيبٍ

Transliteration man kāna yurīdu ḥartha l-ākhirati nazid lahu fī ḥarthihi waman kāna yurīdu ḥartha l-dun'yā nu'tihi min'hā wamā lahu fī l-ākhirati min naṣībin

Yoruba Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbèrò láti gba èso (iṣẹ́ rẹ̀ ní) ọ̀run, A máa ṣe àlékún sí èso rẹ̀ fún un. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì gbèrò láti gba èso (iṣẹ́ rẹ̀ ní) ayé, A máa fún un nínú rẹ̀. Kò sì níí sí ìpín kan kan fún un mọ́ ní ọ̀run.

Verse 21

أَمْ لَهُمْ شُرَكَـٰٓؤُا۟ شَرَعُوا۟ لَهُم مِّنَ ٱلدِّينِ مَا لَمْ يَأْذَنۢ بِهِ ٱللَّهُ ۚ وَلَوْلَا كَلِمَةُ ٱلْفَصْلِ لَقُضِىَ بَيْنَهُمْ ۗ وَإِنَّ ٱلظَّـٰلِمِينَ لَهُمْ عَذَابٌ أَلِيمٌ

Transliteration am lahum shurakāu sharaʿū lahum mina l-dīni mā lam yadhan bihi l-lahu walawlā kalimatu l-faṣli laquḍiya baynahum wa-inna l-ẓālimīna lahum ʿadhābun alīmun

Yoruba Tàbí wọ́n ní àwọn òrìṣà kan tó ṣòfin (ìbọ̀rìṣà) fún wọn nínú ẹ̀sìn, èyí tí Allāhu kò yọ̀ǹda rẹ̀? Tí kò bá jẹ́ ti ọ̀rọ̀ àsọyán (pé A kò níí kánjú jẹ wọ́n ní ìyà), Àwa ìbá ti mú ìdájọ́ wá láààrin wọn. Dájúdájú àwọn alábòsí, ìyà ẹlẹ́ta-eléro sì wà fún wọn.

Verse 22

تَرَى ٱلظَّـٰلِمِينَ مُشْفِقِينَ مِمَّا كَسَبُوا۟ وَهُوَ وَاقِعٌۢ بِهِمْ ۗ وَٱلَّذِينَ ءَامَنُوا۟ وَعَمِلُوا۟ ٱلصَّـٰلِحَـٰتِ فِى رَوْضَاتِ ٱلْجَنَّاتِ ۖ لَهُم مَّا يَشَآءُونَ عِندَ رَبِّهِمْ ۚ ذَٰلِكَ هُوَ ٱلْفَضْلُ ٱلْكَبِيرُ

Transliteration tarā l-ẓālimīna mush'fiqīna mimmā kasabū wahuwa wāqiʿun bihim wa-alladhīna āmanū waʿamilū l-ṣāliḥāti fī rawḍāti l-janāti lahum mā yashāūna ʿinda rabbihim dhālika huwa l-faḍlu l-kabīru

Yoruba O máa rí àwọn alábòsí tí wọn yóò máa páyà nítorí ohun tí wọ́n ṣe níṣẹ́, tí ó sì máa kò lé wọn lórí. Àwọn tó sì gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n ṣe iṣẹ́ rere máa wà ní àwọn àbàtà Ọgbà Ìdẹ̀ra, Ohun tí wọ́n bá ń fẹ́ máa wà fún wọn ní ọ̀dọ̀ Olúwa wọn. Ìyẹn, òhun ni oore àjùlọ tó tóbi.

Verse 23

ذَٰلِكَ ٱلَّذِى يُبَشِّرُ ٱللَّهُ عِبَادَهُ ٱلَّذِينَ ءَامَنُوا۟ وَعَمِلُوا۟ ٱلصَّـٰلِحَـٰتِ ۗ قُل لَّآ أَسْـَٔلُكُمْ عَلَيْهِ أَجْرًا إِلَّا ٱلْمَوَدَّةَ فِى ٱلْقُرْبَىٰ ۗ وَمَن يَقْتَرِفْ حَسَنَةً نَّزِدْ لَهُۥ فِيهَا حُسْنًا ۚ إِنَّ ٱللَّهَ غَفُورٌ شَكُورٌ

Transliteration dhālika alladhī yubashiru l-lahu ʿibādahu alladhīna āmanū waʿamilū l-ṣāliḥāti qul lā asalukum ʿalayhi ajran illā l-mawadata fī l-qur'bā waman yaqtarif ḥasanatan nazid lahu fīhā ḥus'nan inna l-laha ghafūrun shakūrun

Yoruba Ìyẹn ni èyí tí Allāhu fi ń ṣe ìró ìdùnnú fún àwọn ẹrúsìn Rẹ̀, àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe àwọn iṣẹ́ rere. Sọ pé: “Èmi kò bèèrè owó-ọ̀yà lọ́wọ́ yín lórí rẹ̀ bí kò ṣe ìfẹ́ ẹbí.”Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe rere kan, A máa ṣe àlékún rere fún un. Dájúdájú Allāhu ni Aláforíjìn, Ọlọ́pẹ́.2

Verse 24

أَمْ يَقُولُونَ ٱفْتَرَىٰ عَلَى ٱللَّهِ كَذِبًا ۖ فَإِن يَشَإِ ٱللَّهُ يَخْتِمْ عَلَىٰ قَلْبِكَ ۗ وَيَمْحُ ٱللَّهُ ٱلْبَـٰطِلَ وَيُحِقُّ ٱلْحَقَّ بِكَلِمَـٰتِهِۦٓ ۚ إِنَّهُۥ عَلِيمٌۢ بِذَاتِ ٱلصُّدُورِ

Transliteration am yaqūlūna if'tarā ʿalā l-lahi kadhiban fa-in yasha-i l-lahu yakhtim ʿalā qalbika wayamḥu l-lahu l-bāṭila wayuḥiqqu l-ḥaqa bikalimātihi innahu ʿalīmun bidhāti l-ṣudūri

Yoruba Tàbí wọ́n ń wí pé: “Ó dá àdápa irọ́ mọ́ Allāhu ni?” Nítorí náà, tí Allāhu bá fẹ́, Ó máa fi èdídí dí ọkàn rẹ pa. Àti pé Allāhu yóò pa irọ́ rẹ́. Ó sì máa fi òdodo rinlẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ Rẹ̀. Dájúdájú Òun ni Onímọ̀ nípa ohun tó wà nínú igbá-àyà ẹ̀dá.

Verse 25

وَهُوَ ٱلَّذِى يَقْبَلُ ٱلتَّوْبَةَ عَنْ عِبَادِهِۦ وَيَعْفُوا۟ عَنِ ٱلسَّيِّـَٔاتِ وَيَعْلَمُ مَا تَفْعَلُونَ

Transliteration wahuwa alladhī yaqbalu l-tawbata ʿan ʿibādihi wayaʿfū ʿani l-sayiāti wayaʿlamu mā tafʿalūna

Yoruba Òun ni Ẹni tó ń gba ìronúpìwàdà láti ọ̀dọ̀ àwọn ẹrúsìn Rẹ̀. Ó ń ṣe àmójúkúrò níbi àwọn àṣìṣe. Ó sì mọ ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.

Verse 26

وَيَسْتَجِيبُ ٱلَّذِينَ ءَامَنُوا۟ وَعَمِلُوا۟ ٱلصَّـٰلِحَـٰتِ وَيَزِيدُهُم مِّن فَضْلِهِۦ ۚ وَٱلْكَـٰفِرُونَ لَهُمْ عَذَابٌ شَدِيدٌ

Transliteration wayastajību alladhīna āmanū waʿamilū l-ṣāliḥāti wayazīduhum min faḍlihi wal-kāfirūna lahum ʿadhābun shadīdun

Yoruba Ó ń gba àdúà àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe àwọn iṣẹ́ rere. Ó sì ń ṣe àlékún fún wọn nínú ọlá Rẹ̀. Àwọn aláìgbàgbọ́, ìyà líle sì wà fún wọn.

Verse 27

۞ وَلَوْ بَسَطَ ٱللَّهُ ٱلرِّزْقَ لِعِبَادِهِۦ لَبَغَوْا۟ فِى ٱلْأَرْضِ وَلَـٰكِن يُنَزِّلُ بِقَدَرٍ مَّا يَشَآءُ ۚ إِنَّهُۥ بِعِبَادِهِۦ خَبِيرٌۢ بَصِيرٌ

Transliteration walaw basaṭa l-lahu l-riz'qa liʿibādihi labaghaw fī l-arḍi walākin yunazzilu biqadarin mā yashāu innahu biʿibādihi khabīrun baṣīrun

Yoruba Tí ó bá jẹ́ pé Allāhu tẹ́ arísìkí sílẹ̀ rẹgẹdẹ fún àwọn ẹrúsìn Rẹ̀ ni, wọn ìbá tayọ ẹnu-ààlà lórí ilẹ̀. Ṣùgbọ́n Ó ń sọ (arísìkí) tí Ó bá fẹ́ kalẹ̀ níwọ̀n-níwọ̀n. Dájúdájú Òun ni Alámọ̀tán, Olùríran nípa àwọn ẹrúsìn Rẹ̀.

Verse 28

وَهُوَ ٱلَّذِى يُنَزِّلُ ٱلْغَيْثَ مِنۢ بَعْدِ مَا قَنَطُوا۟ وَيَنشُرُ رَحْمَتَهُۥ ۚ وَهُوَ ٱلْوَلِىُّ ٱلْحَمِيدُ

Transliteration wahuwa alladhī yunazzilu l-ghaytha min baʿdi mā qanaṭū wayanshuru raḥmatahu wahuwa l-waliyu l-ḥamīdu

Yoruba Òun sì ni Ẹni tó ń sọ omi òjò kalẹ̀ lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n ti sọ̀rètí nù. Ó sì ń fọ́n ìkẹ́ Rẹ̀ ká. Òun sì ni Aláàbò, Ẹlẹ́yìn.

Verse 29

وَمِنْ ءَايَـٰتِهِۦ خَلْقُ ٱلسَّمَـٰوَٰتِ وَٱلْأَرْضِ وَمَا بَثَّ فِيهِمَا مِن دَآبَّةٍ ۚ وَهُوَ عَلَىٰ جَمْعِهِمْ إِذَا يَشَآءُ قَدِيرٌ

Transliteration wamin āyātihi khalqu l-samāwāti wal-arḍi wamā batha fīhimā min dābbatin wahuwa ʿalā jamʿihim idhā yashāu qadīrun

Yoruba Àti pé nínú àmì Rẹ̀ ni ìṣẹ̀dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ àti n̄ǹkan tí Ó fọ́nká sáààrin méjèèjì nínú àwọn n̄ǹkan abẹ̀mí. Òun sì ni Alágbára lórí ìkójọ wọn nígbà tí Ó bá fẹ́.

Verse 30

وَمَآ أَصَـٰبَكُم مِّن مُّصِيبَةٍ فَبِمَا كَسَبَتْ أَيْدِيكُمْ وَيَعْفُوا۟ عَن كَثِيرٍ

Transliteration wamā aṣābakum min muṣībatin fabimā kasabat aydīkum wayaʿfū ʿan kathīrin

Yoruba Ohunkóhun tí ó bá kàn yín nínú àdánwò, ohun tí ẹ fi ọwọ́ ara yín fà ni.Ó sì ń ṣàmójúkúrò níbi ọ̀pọ̀lọ́pọ̀.

Verse 31

وَمَآ أَنتُم بِمُعْجِزِينَ فِى ٱلْأَرْضِ ۖ وَمَا لَكُم مِّن دُونِ ٱللَّهِ مِن وَلِىٍّ وَلَا نَصِيرٍ

Transliteration wamā antum bimuʿ'jizīna fī l-arḍi wamā lakum min dūni l-lahi min waliyyin walā naṣīrin

Yoruba Ẹ̀yin kò lè mórí bọ́ (mọ́ Allāhu lọ́wọ́) lórí ilẹ̀. Kò sì sí aláàbò àti alárànṣe kan fún yín lẹ́yìn Allāhu.

Verse 32

وَمِنْ ءَايَـٰتِهِ ٱلْجَوَارِ فِى ٱلْبَحْرِ كَٱلْأَعْلَـٰمِ

Transliteration wamin āyātihi l-jawāri fī l-baḥri kal-aʿlāmi

Yoruba Ó tún wà nínú àwọn àmì Rẹ̀, àwọn ọkọ̀ ojú-omi tó ń rìn lójú omi (tó dà) bí àwọn òkè àpáta gíga.

Verse 33

إِن يَشَأْ يُسْكِنِ ٱلرِّيحَ فَيَظْلَلْنَ رَوَاكِدَ عَلَىٰ ظَهْرِهِۦٓ ۚ إِنَّ فِى ذَٰلِكَ لَـَٔايَـٰتٍ لِّكُلِّ صَبَّارٍ شَكُورٍ

Transliteration in yasha yus'kini l-rīḥa fayaẓlalna rawākida ʿalā ẓahrihi inna fī dhālika laāyātin likulli ṣabbārin shakūrin

Yoruba Tí Allāhu bá fẹ́, Ó máa dá atẹ́gùn náà dúró, (àwọn ọkọ̀ ojú-omi náà) sì máa dúró pa sójú kan náà lórí omi. Dájúdájú àwọn àmì wà nínú ìyẹn fún gbogbo onísùúrù, olùdúpẹ́.

Verse 34

أَوْ يُوبِقْهُنَّ بِمَا كَسَبُوا۟ وَيَعْفُ عَن كَثِيرٍ

Transliteration aw yūbiq'hunna bimā kasabū wayaʿfu ʿan kathīrin

Yoruba Tàbí kí Ó kó ìparun bá (àwọn ọkọ̀ ojú-omi náà) nítorí ohun tí àwọn èrò ọkọ̀ ojú-omi ṣe (níṣẹ́ aburú). Ó sì ń ṣàmójúkúrò níbi ọ̀pọ̀lọ́pọ̀.

Verse 35

وَيَعْلَمَ ٱلَّذِينَ يُجَـٰدِلُونَ فِىٓ ءَايَـٰتِنَا مَا لَهُم مِّن مَّحِيصٍ

Transliteration wayaʿlama alladhīna yujādilūna fī āyātinā mā lahum min maḥīṣin

Yoruba Àwọn tó ń (fi irọ́) ja àwọn āyah Wa ní iyàn sì máa mọ̀ pé kò sí ibùsásí kan fún wọn.

Verse 36

فَمَآ أُوتِيتُم مِّن شَىْءٍ فَمَتَـٰعُ ٱلْحَيَوٰةِ ٱلدُّنْيَا ۖ وَمَا عِندَ ٱللَّهِ خَيْرٌ وَأَبْقَىٰ لِلَّذِينَ ءَامَنُوا۟ وَعَلَىٰ رَبِّهِمْ يَتَوَكَّلُونَ

Transliteration famā ūtītum min shayin famatāʿu l-ḥayati l-dun'yā wamā ʿinda l-lahi khayrun wa-abqā lilladhīna āmanū waʿalā rabbihim yatawakkalūna

Yoruba Nítorí náà, ohunkóhun tí A bá fún yín, ìgbádùn ayé nìkan ni. Ohun tí ó wà lọ́dọ̀ Allāhu lóore jùlọ, ó sì máa ṣẹ́kù títí láéláé fún àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ń gbáralé Olúwa wọn.

Verse 37

وَٱلَّذِينَ يَجْتَنِبُونَ كَبَـٰٓئِرَ ٱلْإِثْمِ وَٱلْفَوَٰحِشَ وَإِذَا مَا غَضِبُوا۟ هُمْ يَغْفِرُونَ

Transliteration wa-alladhīna yajtanibūna kabāira l-ith'mi wal-fawāḥisha wa-idhā mā ghaḍibū hum yaghfirūna

Yoruba (Ohun tí ó wà lọ́dọ̀ Allāhu tún wà fún) àwọn tó ń jìnnà sí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ ńlá ńlá àti àwọn ìwà ìbàjẹ́, àti (àwọn tó jẹ́ pé) nígbà tí wọ́n bá bínú, wọn yóò ṣàforíjìn.

Verse 38

وَٱلَّذِينَ ٱسْتَجَابُوا۟ لِرَبِّهِمْ وَأَقَامُوا۟ ٱلصَّلَوٰةَ وَأَمْرُهُمْ شُورَىٰ بَيْنَهُمْ وَمِمَّا رَزَقْنَـٰهُمْ يُنفِقُونَ

Transliteration wa-alladhīna is'tajābū lirabbihim wa-aqāmū l-ṣalata wa-amruhum shūrā baynahum wamimmā razaqnāhum yunfiqūna

Yoruba (Ohun tí ó wà lọ́dọ̀ Allāhu tún wà fún) àwọn tó jẹ́pè ti Olúwa wọn, tí wọ́n ń kírun, ọ̀rọ̀ ara wọn sì jẹ́ ìjíròrò láààrin ara wọn, wọ́n tún ń ná nínú arísìkí tí A pèsè fún wọn.

Verse 39

وَٱلَّذِينَ إِذَآ أَصَابَهُمُ ٱلْبَغْىُ هُمْ يَنتَصِرُونَ

Transliteration wa-alladhīna idhā aṣābahumu l-baghyu hum yantaṣirūna

Yoruba (Ohun tí ó wà lọ́dọ̀ Allāhu tún wà fún) àwọn tí (ó jẹ́ pé) nígbà tí wọ́n bá ṣe àbòsí sí wọn, wọn yóò gbẹ̀san wọn padà.

Verse 40

وَجَزَٰٓؤُا۟ سَيِّئَةٍ سَيِّئَةٌ مِّثْلُهَا ۖ فَمَنْ عَفَا وَأَصْلَحَ فَأَجْرُهُۥ عَلَى ٱللَّهِ ۚ إِنَّهُۥ لَا يُحِبُّ ٱلظَّـٰلِمِينَ

Transliteration wajazāu sayyi-atin sayyi-atun mith'luhā faman ʿafā wa-aṣlaḥa fa-ajruhu ʿalā l-lahi innahu lā yuḥibbu l-ẓālimīna

Yoruba Ẹ̀san aburú sì ni aburú bí irú rẹ̀.Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì ṣàmójúkúrò, tí ó tún ṣàtúnṣe, ẹ̀san rẹ̀ wà lọ́dọ̀ Allāhu. Dájúdájú (Allāhu) kò nífẹ̀ẹ́ àwọn alábòsí.

Verse 41

وَلَمَنِ ٱنتَصَرَ بَعْدَ ظُلْمِهِۦ فَأُو۟لَـٰٓئِكَ مَا عَلَيْهِم مِّن سَبِيلٍ

Transliteration walamani intaṣara baʿda ẓul'mihi fa-ulāika mā ʿalayhim min sabīlin

Yoruba Dájúdájú ẹni tí ó bá sì gbẹ̀san lẹ́yìn tí wọ́n ṣe àbòsí sí i, àwọn wọ̀nyẹn (tí wọ́n ṣàbòsí sí), kò sí ìbáwí kan kan fún wọn.

Verse 42

إِنَّمَا ٱلسَّبِيلُ عَلَى ٱلَّذِينَ يَظْلِمُونَ ٱلنَّاسَ وَيَبْغُونَ فِى ٱلْأَرْضِ بِغَيْرِ ٱلْحَقِّ ۚ أُو۟لَـٰٓئِكَ لَهُمْ عَذَابٌ أَلِيمٌ

Transliteration innamā l-sabīlu ʿalā alladhīna yaẓlimūna l-nāsa wayabghūna fī l-arḍi bighayri l-ḥaqi ulāika lahum ʿadhābun alīmun

Yoruba Àwọn tí ìbáwí wà fún ni àwọn tó ń ṣàbòsí sí àwọn ènìyàn, tí wọ́n tún ń tayọ ẹnu-ààlà lórí ilẹ̀ láì lẹ́tọ̀ọ́. Àwọn wọ̀nyẹn ni ìyà ẹlẹ́ta-eléro wà fún.

Verse 43

وَلَمَن صَبَرَ وَغَفَرَ إِنَّ ذَٰلِكَ لَمِنْ عَزْمِ ٱلْأُمُورِ

Transliteration walaman ṣabara waghafara inna dhālika lamin ʿazmi l-umūri

Yoruba Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe sùúrù, tí ó tún ṣàforíjìn, dájúdájú ìyẹn wà nínú àwọn ìpinnu ọ̀rọ̀.

Verse 44

وَمَن يُضْلِلِ ٱللَّهُ فَمَا لَهُۥ مِن وَلِىٍّ مِّنۢ بَعْدِهِۦ ۗ وَتَرَى ٱلظَّـٰلِمِينَ لَمَّا رَأَوُا۟ ٱلْعَذَابَ يَقُولُونَ هَلْ إِلَىٰ مَرَدٍّ مِّن سَبِيلٍ

Transliteration waman yuḍ'lili l-lahu famā lahu min waliyyin min baʿdihi watarā l-ẓālimīna lammā ra-awū l-ʿadhāba yaqūlūna hal ilā maraddin min sabīlin

Yoruba Ẹnikẹ́ni tí Allāhu bá ṣì lọ́nà, kò tún sí aláàbò kan fún un mọ́ lẹ́yìn Rẹ̀. O sì máa rí àwọn alábòsí nígbà tí wọ́n bá rí Iná, wọn yóò wí pé: “Ǹjẹ́ ọ̀nà kan kan wà tí a lè fi padà sí ilé ayé?”

Verse 45

وَتَرَىٰهُمْ يُعْرَضُونَ عَلَيْهَا خَـٰشِعِينَ مِنَ ٱلذُّلِّ يَنظُرُونَ مِن طَرْفٍ خَفِىٍّ ۗ وَقَالَ ٱلَّذِينَ ءَامَنُوٓا۟ إِنَّ ٱلْخَـٰسِرِينَ ٱلَّذِينَ خَسِرُوٓا۟ أَنفُسَهُمْ وَأَهْلِيهِمْ يَوْمَ ٱلْقِيَـٰمَةِ ۗ أَلَآ إِنَّ ٱلظَّـٰلِمِينَ فِى عَذَابٍ مُّقِيمٍ

Transliteration watarāhum yuʿ'raḍūna ʿalayhā khāshiʿīna mina l-dhuli yanẓurūna min ṭarfin khafiyyin waqāla alladhīna āmanū inna l-khāsirīna alladhīna khasirū anfusahum wa-ahlīhim yawma l-qiyāmati alā inna l-ẓālimīna fī ʿadhābin muqīmin

Yoruba O sì máa rí wọn tí A máa kó wọn lọ sínú Iná; wọn yóò palọ́lọ́ láti ara ìyẹpẹrẹ, wọn yó si máa wò fín-ín-fín. Àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo sì máa sọ pé: “Dájúdájú àwọn ẹni òfò ni àwọn tó ṣe ẹ̀mí ara wọn àti ara ilé wọn ní òfò ní Ọjọ́ Àjíǹde.” Kíyè sí i, dájúdájú àwọn alábòsí yóò wà nínú ìyà gbére.

Verse 46

وَمَا كَانَ لَهُم مِّنْ أَوْلِيَآءَ يَنصُرُونَهُم مِّن دُونِ ٱللَّهِ ۗ وَمَن يُضْلِلِ ٱللَّهُ فَمَا لَهُۥ مِن سَبِيلٍ

Transliteration wamā kāna lahum min awliyāa yanṣurūnahum min dūni l-lahi waman yuḍ'lili l-lahu famā lahu min sabīlin

Yoruba Kò sì níí sí aláàbò kan fún wọn tí ó máa ràn wọ́n lọ́wọ́ lẹ́yìn Allāhu. Àti pé ẹnikẹ́ni tí Allāhu bá ṣì lọ́nà, kò níí sí ọ̀nà kan kan fún un.

Verse 47

ٱسْتَجِيبُوا۟ لِرَبِّكُم مِّن قَبْلِ أَن يَأْتِىَ يَوْمٌ لَّا مَرَدَّ لَهُۥ مِنَ ٱللَّهِ ۚ مَا لَكُم مِّن مَّلْجَإٍ يَوْمَئِذٍ وَمَا لَكُم مِّن نَّكِيرٍ

Transliteration is'tajībū lirabbikum min qabli an yatiya yawmun lā maradda lahu mina l-lahi mā lakum min malja-in yawma-idhin wamā lakum min nakīrin

Yoruba Ẹ jẹ́pè Olúwa yín ṣíwájú kí ọjọ́ kan tí kò ṣe é dá padà tó dé láti ọ̀dọ̀ Allāhu. Kò sí ibùsásí kan fún yín ní ọjọ́ yẹn. Kò sì níí sí ẹni tí ó máa bá yín kọ ìyà náà.

Verse 48

فَإِنْ أَعْرَضُوا۟ فَمَآ أَرْسَلْنَـٰكَ عَلَيْهِمْ حَفِيظًا ۖ إِنْ عَلَيْكَ إِلَّا ٱلْبَلَـٰغُ ۗ وَإِنَّآ إِذَآ أَذَقْنَا ٱلْإِنسَـٰنَ مِنَّا رَحْمَةً فَرِحَ بِهَا ۖ وَإِن تُصِبْهُمْ سَيِّئَةٌۢ بِمَا قَدَّمَتْ أَيْدِيهِمْ فَإِنَّ ٱلْإِنسَـٰنَ كَفُورٌ

Transliteration fa-in aʿraḍū famā arsalnāka ʿalayhim ḥafīẓan in ʿalayka illā l-balāghu wa-innā idhā adhaqnā l-insāna minnā raḥmatan fariḥa bihā wa-in tuṣib'hum sayyi-atun bimā qaddamat aydīhim fa-inna l-insāna kafūrun

Yoruba Nítorí náà, tí wọ́n bá gbúnrí, A kò rán ọ pé kí o jẹ́ olùṣọ́ fún wọn. Kò sí kiní kan tó di dandan fún ọ bí kò ṣe ìkéde (ẹ̀sìn). Àti pé dájúdájú nígbà tí A bá fún ènìyàn ní ìkẹ́ kan tọ́ wò láti ọ̀dọ̀ Wa, ó máa dunnú sí i. Tí aburú kan bá sì kàn án nípasẹ̀ ohun tí ọwọ́ wọn tì ṣíwájú (ní iṣẹ́ aburú), dájúdájú ènìyàn ni aláìmoore.

Verse 49

لِّلَّهِ مُلْكُ ٱلسَّمَـٰوَٰتِ وَٱلْأَرْضِ ۚ يَخْلُقُ مَا يَشَآءُ ۚ يَهَبُ لِمَن يَشَآءُ إِنَـٰثًا وَيَهَبُ لِمَن يَشَآءُ ٱلذُّكُورَ

Transliteration lillahi mul'ku l-samāwāti wal-arḍi yakhluqu mā yashāu yahabu liman yashāu ināthan wayahabu liman yashāu l-dhukūra

Yoruba Ti Allāhu ni ìjọba àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Ó ń ṣẹ̀dá ohun tí Ó bá fẹ́. Ó ń ta ẹni tí Ó bá fẹ́ lọ́rẹ ọmọbìnrin. Ó sì ń ta ẹni tí Ó bá fẹ́ lọ́rẹ ọmọkùnrin.

Verse 50

أَوْ يُزَوِّجُهُمْ ذُكْرَانًا وَإِنَـٰثًا ۖ وَيَجْعَلُ مَن يَشَآءُ عَقِيمًا ۚ إِنَّهُۥ عَلِيمٌ قَدِيرٌ

Transliteration aw yuzawwijuhum dhuk'rānan wa-ināthan wayajʿalu man yashāu ʿaqīman innahu ʿalīmun qadīrun

Yoruba Tàbí kí Ó ṣe wọ́n ní oríṣi méjì; ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin. Ó sì ń ṣe ẹni tí Ó bá fẹ́ ní àgàn. Dájúdájú Òun ni Onímọ̀, Alágbára.

Verse 51

۞ وَمَا كَانَ لِبَشَرٍ أَن يُكَلِّمَهُ ٱللَّهُ إِلَّا وَحْيًا أَوْ مِن وَرَآئِ حِجَابٍ أَوْ يُرْسِلَ رَسُولًا فَيُوحِىَ بِإِذْنِهِۦ مَا يَشَآءُ ۚ إِنَّهُۥ عَلِىٌّ حَكِيمٌ

Transliteration wamā kāna libasharin an yukallimahu l-lahu illā waḥyan aw min warāi ḥijābin aw yur'sila rasūlan fayūḥiya bi-idh'nihi mā yashāu innahu ʿaliyyun ḥakīmun

Yoruba Kò lẹ́tọ̀ọ́ fún abara kan pé kí Allāhu bá a sọ̀rọ̀ àfi kí (ọ̀rọ̀ náà) jẹ́ ìmísí (ìṣípayá mímọ́), tàbí kí ó jẹ́ lẹ́yìn gàgá, tàbí kí Ó rán Òjíṣẹ́ kan (tí ó jẹ́ mọlāika) sí i, ó sì máa fi ìmísí jíṣẹ́ fún (abara náà) pẹ̀lú ìyọ̀ǹda (Allāhu). Dájúdájú Ó ga. Ọlọ́gbọ́n sì ni.

Verse 52

وَكَذَٰلِكَ أَوْحَيْنَآ إِلَيْكَ رُوحًا مِّنْ أَمْرِنَا ۚ مَا كُنتَ تَدْرِى مَا ٱلْكِتَـٰبُ وَلَا ٱلْإِيمَـٰنُ وَلَـٰكِن جَعَلْنَـٰهُ نُورًا نَّهْدِى بِهِۦ مَن نَّشَآءُ مِنْ عِبَادِنَا ۚ وَإِنَّكَ لَتَهْدِىٓ إِلَىٰ صِرَٰطٍ مُّسْتَقِيمٍ

Transliteration wakadhālika awḥaynā ilayka rūḥan min amrinā mā kunta tadrī mā l-kitābu walā l-īmānu walākin jaʿalnāhu nūran nahdī bihi man nashāu min ʿibādinā wa-innaka latahdī ilā ṣirāṭin mus'taqīmin

Yoruba Báyẹn sì ni A ṣe fi ìmísí ránṣẹ́ sí ọ nínú àṣẹ Wa. Ìwọ kò mọ kí ni Tírà àti ìgbàgbọ́ òdodo tẹ́lẹ̀ (ṣíwájú ìmísí náà),ṣùgbọ́n A ṣe ìmísí náà ní ìmọ́lẹ̀ kan tí À ń fi ṣe ìmọ̀nà fún ẹni tí A bá fẹ́ nínú àwọn ẹrúsìn Wa. Dájúdájú ìwọ ń pèpè sí ọ̀nà tààrà (’Islām).2

Verse 53

صِرَٰطِ ٱللَّهِ ٱلَّذِى لَهُۥ مَا فِى ٱلسَّمَـٰوَٰتِ وَمَا فِى ٱلْأَرْضِ ۗ أَلَآ إِلَى ٱللَّهِ تَصِيرُ ٱلْأُمُورُ

Transliteration ṣirāṭi l-lahi alladhī lahu mā fī l-samāwāti wamā fī l-arḍi alā ilā l-lahi taṣīru l-umūru

Yoruba Ọ̀nà Allāhu, Ẹni tí ohunkóhun tó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ohunkóhun tó wà nínú ilẹ̀ ń jẹ́ tiRẹ̀. Gbọ́! Ọ̀dọ̀ Allāhu ni àwọn ọ̀rọ̀ ẹ̀dá yóò padà sí.

Read Surah Ash-Shuraa in another language

All languages

All 114 surahs in Yoruba: the Qur’an in Yoruba.

Learn it in MyDugsi

Yoruba translation: Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni, from Quran.com. Transliteration: Quran.com. Recitation: Mishary Alafasy, from EveryAyah.com. MyDugsi is a learning aid, not a replacement for a qualified teacher.