MyDugsiStart learning

Surah Al-Ghashiyah in Yoruba: translation and audio

Surah 88 · الغاشية · The Overwhelming · 26 verses

Surah Al-Ghashiyah verse by verse: the Arabic with a recitation you can repeat, the transliteration, and the Yoruba translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni. For the meaning of every word, see Surah Al-Ghashiyah word by word in English.

Verse 1

هَلْ أَتَىٰكَ حَدِيثُ ٱلْغَـٰشِيَةِ

Transliteration hal atāka ḥadīthu l-ghāshiyati

Yoruba Ṣebí ọ̀rọ̀ nípa ohun tó máa bo ẹ̀dá mọ́lẹ̀ ti dé ọ̀dọ̀ rẹ?

Verse 2

وُجُوهٌ يَوْمَئِذٍ خَـٰشِعَةٌ

Transliteration wujūhun yawma-idhin khāshiʿatun

Yoruba Àwọn ojú kan yóò wálẹ̀ (ní ti ìyẹpẹrẹ) ní ọjọ́ yẹn.

Verse 3

عَامِلَةٌ نَّاصِبَةٌ

Transliteration ʿāmilatun nāṣibatun

Yoruba Wọ́n ṣe iṣẹ́ àṣekúdórógbó (ni nílé ayé).

Verse 4

تَصْلَىٰ نَارًا حَامِيَةً

Transliteration taṣlā nāran ḥāmiyatan

Yoruba Wọ́n sì máa wọ inú Iná tó gbóná janjan (ní ọ̀run).

Verse 5

تُسْقَىٰ مِنْ عَيْنٍ ءَانِيَةٍ

Transliteration tus'qā min ʿaynin āniyatin

Yoruba Wọ́n sì máa fún (wọn) ní omi ìṣẹ́lẹ̀rú gbígbóná mu.

Verse 6

لَّيْسَ لَهُمْ طَعَامٌ إِلَّا مِن ضَرِيعٍ

Transliteration laysa lahum ṭaʿāmun illā min ḍarīʿin

Yoruba Kò sí oúnjẹ kan fún wọn àyàfi igi ẹlẹ́gùn-ún gbígbẹ.

Verse 7

لَّا يُسْمِنُ وَلَا يُغْنِى مِن جُوعٍ

Transliteration lā yus'minu walā yugh'nī min jūʿin

Yoruba Kò níí mú wọn sanra. Kò sì níí rọ̀ wọ́n lọ́rọ̀ nínú ebi.

Verse 8

وُجُوهٌ يَوْمَئِذٍ نَّاعِمَةٌ

Transliteration wujūhun yawma-idhin nāʿimatun

Yoruba Àwọn ojú kan yó sì kún fún ìgbádùn ní ọjọ́ yẹn

Verse 9

لِّسَعْيِهَا رَاضِيَةٌ

Transliteration lisaʿyihā rāḍiyatun

Yoruba nítorí pé (ó) yọ́nú sí (ẹ̀san) iṣẹ́ rẹ̀.

Verse 10

فِى جَنَّةٍ عَالِيَةٍ

Transliteration fī jannatin ʿāliyatin

Yoruba (Ó máa) wà nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra gíga.

Verse 11

لَّا تَسْمَعُ فِيهَا لَـٰغِيَةً

Transliteration lā tasmaʿu fīhā lāghiyatan

Yoruba Wọn kò níí gbọ́ ìsọkúsọ nínú rẹ̀.

Verse 12

فِيهَا عَيْنٌ جَارِيَةٌ

Transliteration fīhā ʿaynun jāriyatun

Yoruba Omi ìṣẹ́lẹ̀rú tó ń ṣàn wà nínú rẹ̀.

Verse 13

فِيهَا سُرُرٌ مَّرْفُوعَةٌ

Transliteration fīhā sururun marfūʿatun

Yoruba Àwọn ibùsùn tí wọ́n gbé sókè wà nínú rẹ̀,

Verse 14

وَأَكْوَابٌ مَّوْضُوعَةٌ

Transliteration wa-akwābun mawḍūʿatun

Yoruba àti àwọn ife ìmumi tí wọ́n gbé kalẹ̀ (sí àrọ́wọ́tó wọn),

Verse 15

وَنَمَارِقُ مَصْفُوفَةٌ

Transliteration wanamāriqu maṣfūfatun

Yoruba àti àwọn ìrọ̀rí tí wọ́n tò sí ẹ̀gbẹ́ ara wọn,

Verse 16

وَزَرَابِىُّ مَبْثُوثَةٌ

Transliteration wazarābiyyu mabthūthatun

Yoruba àti àwọn ìtẹ́ àtẹ́ẹ̀ká.

Verse 17

أَفَلَا يَنظُرُونَ إِلَى ٱلْإِبِلِ كَيْفَ خُلِقَتْ

Transliteration afalā yanẓurūna ilā l-ibili kayfa khuliqat

Yoruba Nítorí náà, ṣé wọn kò wòye sí ràkúnmí, bí A ti ṣẹ̀dá rẹ̀ ni;

Verse 18

وَإِلَى ٱلسَّمَآءِ كَيْفَ رُفِعَتْ

Transliteration wa-ilā l-samāi kayfa rufiʿat

Yoruba àti sánmọ̀, bí A ti ṣe gbé e sókè;

Verse 19

وَإِلَى ٱلْجِبَالِ كَيْفَ نُصِبَتْ

Transliteration wa-ilā l-jibāli kayfa nuṣibat

Yoruba àti àpáta, bí A ti ṣe gbé e nàró (sínú ilẹ̀);

Verse 20

وَإِلَى ٱلْأَرْضِ كَيْفَ سُطِحَتْ

Transliteration wa-ilā l-arḍi kayfa suṭiḥat

Yoruba àti ilẹ̀, bí A ti ṣe tẹ́ ẹ sílẹ̀ pẹrẹsẹ?

Verse 21

فَذَكِّرْ إِنَّمَآ أَنتَ مُذَكِّرٌ

Transliteration fadhakkir innamā anta mudhakkirun

Yoruba Nítorí náà, ṣèrántí. Ìwọ kúkú ni olùṣèràntí.

Verse 22

لَّسْتَ عَلَيْهِم بِمُصَيْطِرٍ

Transliteration lasta ʿalayhim bimuṣayṭirin

Yoruba Ìwọ kì í ṣe ajẹni-nípá lórí wọn

Verse 23

إِلَّا مَن تَوَلَّىٰ وَكَفَرَ

Transliteration illā man tawallā wakafara

Yoruba àfi ẹni tí ó bá pẹ̀yìndà (sí òdodo), tí ó sì ṣàì gbàgbọ́.

Verse 24

فَيُعَذِّبُهُ ٱللَّهُ ٱلْعَذَابَ ٱلْأَكْبَرَ

Transliteration fayuʿadhibuhu l-lahu l-ʿadhāba l-akbara

Yoruba Allāhu sì máa jẹ ẹ́ níyà tó tóbi jùlọ.

Verse 25

إِنَّ إِلَيْنَآ إِيَابَهُمْ

Transliteration inna ilaynā iyābahum

Yoruba Dájúdájú ọ̀dọ̀ Wa ni àbọ̀ wọn wà.

Verse 26

ثُمَّ إِنَّ عَلَيْنَا حِسَابَهُم

Transliteration thumma inna ʿalaynā ḥisābahum

Yoruba Lẹ́yìn náà, dájúdájú Àwa l’A máa ṣe ìṣírò-iṣẹ́ wọn.

Read Surah Al-Ghashiyah in another language

All languages

All 114 surahs in Yoruba: the Qur’an in Yoruba.

Learn it in MyDugsi

Yoruba translation: Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni, from Quran.com. Transliteration: Quran.com. Recitation: Mishary Alafasy, from EveryAyah.com. MyDugsi is a learning aid, not a replacement for a qualified teacher.