Surah Al-Anfal in Yoruba: translation and audio
Surah 8 · الأنفال · The Spoils of War · 75 verses
Surah Al-Anfal verse by verse: the Arabic with a recitation you can repeat, the transliteration, and the Yoruba translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni. For the meaning of every word, see Surah Al-Anfal word by word in English.
Verse 1
يَسْـَٔلُونَكَ عَنِ ٱلْأَنفَالِ ۖ قُلِ ٱلْأَنفَالُ لِلَّهِ وَٱلرَّسُولِ ۖ فَٱتَّقُوا۟ ٱللَّهَ وَأَصْلِحُوا۟ ذَاتَ بَيْنِكُمْ ۖ وَأَطِيعُوا۟ ٱللَّهَ وَرَسُولَهُۥٓ إِن كُنتُم مُّؤْمِنِينَ
Transliteration yasalūnaka ʿani l-anfāli quli l-anfālu lillahi wal-rasūli fa-ittaqū l-laha wa-aṣliḥū dhāta baynikum wa-aṭīʿū l-laha warasūlahu in kuntum mu'minīna
Yoruba Wọ́n ń bi ọ́ léèrè nípa ọrọ̀ ogun. Sọ pé: “Ọrọ̀ ogun jẹ́ ti Allāhu àti ti Òjíṣẹ́. Nítorí náà, ẹ bẹ̀rù Allāhu. Kí ẹ sì ṣe àtúnṣe n̄ǹkan tí ń bẹ láààrin yín. Ẹ tẹ̀lé ti Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀ tí ẹ bá jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo.
Verse 2
إِنَّمَا ٱلْمُؤْمِنُونَ ٱلَّذِينَ إِذَا ذُكِرَ ٱللَّهُ وَجِلَتْ قُلُوبُهُمْ وَإِذَا تُلِيَتْ عَلَيْهِمْ ءَايَـٰتُهُۥ زَادَتْهُمْ إِيمَـٰنًا وَعَلَىٰ رَبِّهِمْ يَتَوَكَّلُونَ
Transliteration innamā l-mu'minūna alladhīna idhā dhukira l-lahu wajilat qulūbuhum wa-idhā tuliyat ʿalayhim āyātuhu zādathum īmānan waʿalā rabbihim yatawakkalūna
Yoruba Àwọn onígbàgbọ́ òdodo ni àwọn tó jẹ́ pé nígbà tí wọ́n bá fi (ìyà) Allāhu ṣe ìrántí (fún wọn), ọkàn wọn yóò wárìrì, nígbà tí wọ́n bá sì ké àwọn āyah Rẹ̀ fún wọn, wọn yóò lékún ní ìgbàgbọ́ òdodo. Olúwa wọn sì ni wọ́n ń gbáralé.
Verse 3
ٱلَّذِينَ يُقِيمُونَ ٱلصَّلَوٰةَ وَمِمَّا رَزَقْنَـٰهُمْ يُنفِقُونَ
Transliteration alladhīna yuqīmūna l-ṣalata wamimmā razaqnāhum yunfiqūna
Yoruba (Àwọn ni) àwọn tó ń kírun, tí wọ́n sì ń ná nínú ohun tí A pèsè fún wọn.
Verse 4
أُو۟لَـٰٓئِكَ هُمُ ٱلْمُؤْمِنُونَ حَقًّا ۚ لَّهُمْ دَرَجَـٰتٌ عِندَ رَبِّهِمْ وَمَغْفِرَةٌ وَرِزْقٌ كَرِيمٌ
Transliteration ulāika humu l-mu'minūna ḥaqqan lahum darajātun ʿinda rabbihim wamaghfiratun wariz'qun karīmun
Yoruba Ní òdodo, àwọn wọ̀nyẹn ni onígbàgbọ́ òdodo. Àwọn ipò gíga, àforíjìn àti arísìkí alápọ̀n-ọ́nlé ń bẹ fún wọn lọ́dọ̀ Olúwa wọn.
Verse 5
كَمَآ أَخْرَجَكَ رَبُّكَ مِنۢ بَيْتِكَ بِٱلْحَقِّ وَإِنَّ فَرِيقًا مِّنَ ٱلْمُؤْمِنِينَ لَكَـٰرِهُونَ
Transliteration kamā akhrajaka rabbuka min baytika bil-ḥaqi wa-inna farīqan mina l-mu'minīna lakārihūna
Yoruba Gẹ́gẹ́ bí Olúwa rẹ ṣe mú ọ jáde (lọ sí ojú ogun) láti inú ilé rẹ pẹ̀lú òdodo, dájúdájú igun kan nínú àwọn onígbàgbọ́ ni ẹ̀mí wọn kórira rẹ̀.
Verse 6
يُجَـٰدِلُونَكَ فِى ٱلْحَقِّ بَعْدَ مَا تَبَيَّنَ كَأَنَّمَا يُسَاقُونَ إِلَى ٱلْمَوْتِ وَهُمْ يَنظُرُونَ
Transliteration yujādilūnaka fī l-ḥaqi baʿdamā tabayyana ka-annamā yusāqūna ilā l-mawti wahum yanẓurūna
Yoruba Wọ́n sì ń takò ọ́ níbi òdodo lẹ́yìn tí ó ti fojú hàn (sí wọn) àfi bí ẹni pé wọ́n ń wà wọ́n lọ sí ọ̀dọ̀ ikú, tí wọ́n sì ń wò ó (báyìí).
Verse 7
وَإِذْ يَعِدُكُمُ ٱللَّهُ إِحْدَى ٱلطَّآئِفَتَيْنِ أَنَّهَا لَكُمْ وَتَوَدُّونَ أَنَّ غَيْرَ ذَاتِ ٱلشَّوْكَةِ تَكُونُ لَكُمْ وَيُرِيدُ ٱللَّهُ أَن يُحِقَّ ٱلْحَقَّ بِكَلِمَـٰتِهِۦ وَيَقْطَعَ دَابِرَ ٱلْكَـٰفِرِينَ
Transliteration wa-idh yaʿidukumu l-lahu iḥ'dā l-ṭāifatayni annahā lakum watawaddūna anna ghayra dhāti l-shawkati takūnu lakum wayurīdu l-lahu an yuḥiqqa l-ḥaqa bikalimātihi wayaqṭaʿa dābira l-kāfirīna
Yoruba (Rántí) nígbà tí Allāhu ṣàdéhùn ọ̀kan nínú àwọn ìjọ méjèèjì fún yín pé ó máa jẹ́ tiyín, ẹ̀yin sì ń fẹ́ kí ìjọ tí kò dira ogun jẹ́ tiyín. Allāhu sì fẹ́ mú òdodo ṣẹ pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ Rẹ̀, Ó sì (fẹ́) pa àwọn aláìgbàgbọ́ run pátápátá
Verse 8
لِيُحِقَّ ٱلْحَقَّ وَيُبْطِلَ ٱلْبَـٰطِلَ وَلَوْ كَرِهَ ٱلْمُجْرِمُونَ
Transliteration liyuḥiqqa l-ḥaqa wayub'ṭila l-bāṭila walaw kariha l-muj'rimūna
Yoruba nítorí kí (Allāhu) lè fi òdodo (’Islām) rinlẹ̀ ní òdodo, kí Ó sì lè paná irọ́ (ìbọ̀rìṣà), àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ (ọ̀ṣẹbọ) ìbáà kórira rẹ̀.
Verse 9
إِذْ تَسْتَغِيثُونَ رَبَّكُمْ فَٱسْتَجَابَ لَكُمْ أَنِّى مُمِدُّكُم بِأَلْفٍ مِّنَ ٱلْمَلَـٰٓئِكَةِ مُرْدِفِينَ
Transliteration idh tastaghīthūna rabbakum fa-is'tajāba lakum annī mumiddukum bi-alfin mina l-malāikati mur'difīna
Yoruba (Rántí) nígbà tí ẹ̀ ń wá ìrànlọ́wọ́ Olúwa yín, Ó sì da yín lóhùn pé dájúdájú Èmi yóò ràn yín lọ́wọ́ pẹ̀lú ẹgbẹ̀rún kan nínú àwọn mọlāika tó máa wá ní tẹ̀léǹtẹ̀lé.
Verse 10
وَمَا جَعَلَهُ ٱللَّهُ إِلَّا بُشْرَىٰ وَلِتَطْمَئِنَّ بِهِۦ قُلُوبُكُمْ ۚ وَمَا ٱلنَّصْرُ إِلَّا مِنْ عِندِ ٱللَّهِ ۚ إِنَّ ٱللَّهَ عَزِيزٌ حَكِيمٌ
Transliteration wamā jaʿalahu l-lahu illā bush'rā walitaṭma-inna bihi qulūbukum wamā l-naṣru illā min ʿindi l-lahi inna l-laha ʿazīzun ḥakīmun
Yoruba Allāhu kò sì ṣe (ìrànlọ́wọ́ àwọn mọlāika) lásán bí kò ṣe nítorí kí ó lè jẹ́ ìró ìdùnnú àti nítorí kí ọkàn yín lè balẹ̀ pẹ̀lú rẹ̀. Kò sí àrànṣe kan àfi láti ọ̀dọ̀ Allāhu. Dájúdájú Allāhu ni Alágbára, Ọlọ́gbọ́n.
Verse 11
إِذْ يُغَشِّيكُمُ ٱلنُّعَاسَ أَمَنَةً مِّنْهُ وَيُنَزِّلُ عَلَيْكُم مِّنَ ٱلسَّمَآءِ مَآءً لِّيُطَهِّرَكُم بِهِۦ وَيُذْهِبَ عَنكُمْ رِجْزَ ٱلشَّيْطَـٰنِ وَلِيَرْبِطَ عَلَىٰ قُلُوبِكُمْ وَيُثَبِّتَ بِهِ ٱلْأَقْدَامَ
Transliteration idh yughashīkumu l-nuʿāsa amanatan min'hu wayunazzilu ʿalaykum mina l-samāi māan liyuṭahhirakum bihi wayudh'hiba ʿankum rij'za l-shayṭāni waliyarbiṭa ʿalā qulūbikum wayuthabbita bihi l-aqdāma
Yoruba (Rántí) nígbà tí (Allāhu) ta yín ní òògbé lọ (kí ó lè jẹ́) ìfọ̀kànbalẹ̀ (fún yín) láti ọ̀dọ̀ Rẹ̀. Ó tún sọ omi kalẹ̀ fún yín láti sánmọ̀ nítorí kí Ó fi lè fọ̀ yín mọ́ (pẹ̀lú ìwẹ̀ ọ̀ran-anyàn), àti nítorí kí Ó fi lè mú èròkérò Èṣù (bí àlá ìbálòpò ojú oorun) kúrò fún yín àti nítorí kí Ó lè kì yín lọ́kàn àti nítorí kí Ó lè mú ẹsẹ̀ yín dúró ṣinṣin.
Verse 12
إِذْ يُوحِى رَبُّكَ إِلَى ٱلْمَلَـٰٓئِكَةِ أَنِّى مَعَكُمْ فَثَبِّتُوا۟ ٱلَّذِينَ ءَامَنُوا۟ ۚ سَأُلْقِى فِى قُلُوبِ ٱلَّذِينَ كَفَرُوا۟ ٱلرُّعْبَ فَٱضْرِبُوا۟ فَوْقَ ٱلْأَعْنَاقِ وَٱضْرِبُوا۟ مِنْهُمْ كُلَّ بَنَانٍ
Transliteration idh yūḥī rabbuka ilā l-malāikati annī maʿakum fathabbitū alladhīna āmanū sa-ul'qī fī qulūbi alladhīna kafarū l-ruʿ'ba fa-iḍ'ribū fawqa l-aʿnāqi wa-iḍ'ribū min'hum kulla banānin
Yoruba (Rántí) nígbà tí Olúwa rẹ fi mọ àwọn mọlāika pé dájúdájú Èmi ń bẹ pẹ̀lú yín. Nítorí náà, ẹ fi ẹsẹ̀ àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo rinlẹ̀. Èmi yóò ju ẹ̀rù sínú ọkàn àwọn tó ṣàì gbàgbọ́. Nítorí náà, ẹ máa gé (wọn) lọ́rùn. Kí ẹ sì máa gé gbogbo ọmọ ìka wọn.
Verse 13
ذَٰلِكَ بِأَنَّهُمْ شَآقُّوا۟ ٱللَّهَ وَرَسُولَهُۥ ۚ وَمَن يُشَاقِقِ ٱللَّهَ وَرَسُولَهُۥ فَإِنَّ ٱللَّهَ شَدِيدُ ٱلْعِقَابِ
Transliteration dhālika bi-annahum shāqqū l-laha warasūlahu waman yushāqiqi l-laha warasūlahu fa-inna l-laha shadīdu l-ʿiqābi
Yoruba Ìyẹn nítorí pé, wọ́n yapa (ọ̀rọ̀) Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì yapa (ọ̀rọ̀) Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀, dájúdájú Allāhu le (níbi) ìyà.
Verse 14
ذَٰلِكُمْ فَذُوقُوهُ وَأَنَّ لِلْكَـٰفِرِينَ عَذَابَ ٱلنَّارِ
Transliteration dhālikum fadhūqūhu wa-anna lil'kāfirīna ʿadhāba l-nāri
Yoruba Ìyẹn (ni ìyà tayé). Nítorí náà, ẹ tọ́ ọ wò. Àti pé dájúdájú ìyà Iná ń bẹ fún àwọn aláìgbàgbọ́.
Verse 15
يَـٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُوٓا۟ إِذَا لَقِيتُمُ ٱلَّذِينَ كَفَرُوا۟ زَحْفًا فَلَا تُوَلُّوهُمُ ٱلْأَدْبَارَ
Transliteration yāayyuhā alladhīna āmanū idhā laqītumu alladhīna kafarū zaḥfan falā tuwallūhumu l-adbāra
Yoruba Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, nígbà tí ẹ bá pàdé àwọn tó ṣàì gbàgbọ́, tí wọ́n ń wọ́ jáde níkọ̀ níkọ̀, ẹ̀yin kò gbọdọ̀ pẹ̀yìn dà sí wọn (láti ságun).
Verse 16
وَمَن يُوَلِّهِمْ يَوْمَئِذٍ دُبُرَهُۥٓ إِلَّا مُتَحَرِّفًا لِّقِتَالٍ أَوْ مُتَحَيِّزًا إِلَىٰ فِئَةٍ فَقَدْ بَآءَ بِغَضَبٍ مِّنَ ٱللَّهِ وَمَأْوَىٰهُ جَهَنَّمُ ۖ وَبِئْسَ ٱلْمَصِيرُ
Transliteration waman yuwallihim yawma-idhin duburahu illā mutaḥarrifan liqitālin aw mutaḥayyizan ilā fi-atin faqad bāa bighaḍabin mina l-lahi wamawāhu jahannamu wabi'sa l-maṣīru
Yoruba Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì pẹ̀yìn dà sí wọn ní ọjọ́ yẹn, yàtọ̀ sí ẹni tó yẹ̀ sí ẹ̀gbẹ́ kan (láti túnra mú) fún ogun tàbí ẹni tó fẹ́ darapọ̀ mọ́ ikọ̀ (mùsùlùmí láti fún wọn ní ìró ọ̀tẹlẹ̀-múyẹ́), dájúdájú (aságun) ti padà wálé pẹ̀lú ìbínú láti ọ̀dọ̀ Allāhu. Iná Jahanamọ sì ni ibùgbé rẹ̀. Ìkángun náà sì burú.
Verse 17
فَلَمْ تَقْتُلُوهُمْ وَلَـٰكِنَّ ٱللَّهَ قَتَلَهُمْ ۚ وَمَا رَمَيْتَ إِذْ رَمَيْتَ وَلَـٰكِنَّ ٱللَّهَ رَمَىٰ ۚ وَلِيُبْلِىَ ٱلْمُؤْمِنِينَ مِنْهُ بَلَآءً حَسَنًا ۚ إِنَّ ٱللَّهَ سَمِيعٌ عَلِيمٌ
Transliteration falam taqtulūhum walākinna l-laha qatalahum wamā ramayta idh ramayta walākinna l-laha ramā waliyub'liya l-mu'minīna min'hu balāan ḥasanan inna l-laha samīʿun ʿalīmun
Yoruba Ẹ̀yin kọ́ lẹ pa wọ́n, ṣùgbọ́n Allāhu l’Ó pa wọ́n. Àti pé ìwọ kọ́ lo jùkò nígbà tí o jùkò, àmọ́ dájúdájú Allāhu l’Ó jùkònítorí kí (Allāhu) lè fi àmìwò dáadáa kan àwọn onígbàgbọ́ òdodo láti ọ̀dọ̀ Rẹ̀ ni. Dájúdájú Allāhu ni Olùgbọ́, Onímọ̀.
Verse 18
ذَٰلِكُمْ وَأَنَّ ٱللَّهَ مُوهِنُ كَيْدِ ٱلْكَـٰفِرِينَ
Transliteration dhālikum wa-anna l-laha mūhinu kaydi l-kāfirīna
Yoruba Ìyẹn (báyẹn). Dájúdájú Allāhu máa sọ ète àwọn aláìgbàgbọ́ di lílẹ.
Verse 19
إِن تَسْتَفْتِحُوا۟ فَقَدْ جَآءَكُمُ ٱلْفَتْحُ ۖ وَإِن تَنتَهُوا۟ فَهُوَ خَيْرٌ لَّكُمْ ۖ وَإِن تَعُودُوا۟ نَعُدْ وَلَن تُغْنِىَ عَنكُمْ فِئَتُكُمْ شَيْـًٔا وَلَوْ كَثُرَتْ وَأَنَّ ٱللَّهَ مَعَ ٱلْمُؤْمِنِينَ
Transliteration in tastaftiḥū faqad jāakumu l-fatḥu wa-in tantahū fahuwa khayrun lakum wa-in taʿūdū naʿud walan tugh'niya ʿankum fi-atukum shayan walaw kathurat wa-anna l-laha maʿa l-mu'minīna
Yoruba Tí ẹ̀yin (aláìgbàgbọ́) bá ń wá ìdájọ́, dájúdájú ìdájọ́ ti kò le yín lórí. Tí ẹ bá jáwọ́ (níbi ogun), ó sì dára jùlọ fún yín. Tí ẹ bá tún padà (síbi ogun), A máa padà (ran àwọn onígbàgbọ́ òdodo lọ́wọ́); àkójọ yín kò sì níí rọ̀ yín lọ́rọ̀ kan kan, ìbáà pọ̀. Dájúdájú Allāhu ń bẹ pẹ̀lú àwọn onígbàgbọ́ òdodo.
Verse 20
يَـٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُوٓا۟ أَطِيعُوا۟ ٱللَّهَ وَرَسُولَهُۥ وَلَا تَوَلَّوْا۟ عَنْهُ وَأَنتُمْ تَسْمَعُونَ
Transliteration yāayyuhā alladhīna āmanū aṭīʿū l-laha warasūlahu walā tawallaw ʿanhu wa-antum tasmaʿūna
Yoruba Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ tẹ̀lé ti Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀. Ẹ má ṣe gbúnrí kúrò ní ọ̀dọ̀ rẹ̀ nígbà tí ẹ bá ń gbọ́ (āyah) lọ́wọ́.
Verse 21
وَلَا تَكُونُوا۟ كَٱلَّذِينَ قَالُوا۟ سَمِعْنَا وَهُمْ لَا يَسْمَعُونَ
Transliteration walā takūnū ka-alladhīna qālū samiʿ'nā wahum lā yasmaʿūna
Yoruba Ẹ má se dà bí àwọn tí wọ́n wí pé: “A gbọ́.” Wọn kò sì gbọ́.
Verse 22
۞ إِنَّ شَرَّ ٱلدَّوَآبِّ عِندَ ٱللَّهِ ٱلصُّمُّ ٱلْبُكْمُ ٱلَّذِينَ لَا يَعْقِلُونَ
Transliteration inna sharra l-dawābi ʿinda l-lahi l-ṣumu l-buk'mu alladhīna lā yaʿqilūna
Yoruba Dájúdájú ẹ̀dá abẹ̀mí tó burú jùlọ ní ọ̀dọ̀ Allāhu ni àwọn adití, ayaya tí kò ṣe làákàyè.
Verse 23
وَلَوْ عَلِمَ ٱللَّهُ فِيهِمْ خَيْرًا لَّأَسْمَعَهُمْ ۖ وَلَوْ أَسْمَعَهُمْ لَتَوَلَّوا۟ وَّهُم مُّعْرِضُونَ
Transliteration walaw ʿalima l-lahu fīhim khayran la-asmaʿahum walaw asmaʿahum latawallaw wahum muʿ'riḍūna
Yoruba Tí ó bá jẹ́ pé Allāhu mọ oore kan lára wọn ni, ìbá jẹ́ kí wọ́n gbọ́. Tí (Allāhu) bá sì fún wọn gbọ́ ni, dájúdájú wọn máa pẹ̀yìn dà, wọn yó sì máa gbúnrí.
Verse 24
يَـٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُوا۟ ٱسْتَجِيبُوا۟ لِلَّهِ وَلِلرَّسُولِ إِذَا دَعَاكُمْ لِمَا يُحْيِيكُمْ ۖ وَٱعْلَمُوٓا۟ أَنَّ ٱللَّهَ يَحُولُ بَيْنَ ٱلْمَرْءِ وَقَلْبِهِۦ وَأَنَّهُۥٓ إِلَيْهِ تُحْشَرُونَ
Transliteration yāayyuhā alladhīna āmanū is'tajībū lillahi walilrrasūli idhā daʿākum limā yuḥ'yīkum wa-iʿ'lamū anna l-laha yaḥūlu bayna l-mari waqalbihi wa-annahu ilayhi tuḥ'sharūna
Yoruba Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ jẹ́pè ti Allāhu àti ti Òjíṣẹ́ nígbà tí ó bá pè yín síbi n̄ǹkan tí ó máa mu yín ṣẹ̀mí. Kí ẹ sì mọ̀ pé dájúdájú Allāhu ń ṣèdíwọ́ láààrin ènìyàn àti ọkàn rẹ̀. Dájúdájú ọ̀dọ̀ Rẹ̀ sì ni wọ́n máa ko yín jọ sí.
Verse 25
وَٱتَّقُوا۟ فِتْنَةً لَّا تُصِيبَنَّ ٱلَّذِينَ ظَلَمُوا۟ مِنكُمْ خَآصَّةً ۖ وَٱعْلَمُوٓا۟ أَنَّ ٱللَّهَ شَدِيدُ ٱلْعِقَابِ
Transliteration wa-ittaqū fit'natan lā tuṣībanna alladhīna ẓalamū minkum khāṣṣatan wa-iʿ'lamū anna l-laha shadīdu l-ʿiqābi
Yoruba Ẹ ṣọrá fún àdánwò kan tí kò níí mọ lórí àwọn tó ṣàbòsí nínú yín nìkan. Kí ẹ sì mọ̀ pé dájúdájú Allāhu le níbi ìyà.
Verse 26
وَٱذْكُرُوٓا۟ إِذْ أَنتُمْ قَلِيلٌ مُّسْتَضْعَفُونَ فِى ٱلْأَرْضِ تَخَافُونَ أَن يَتَخَطَّفَكُمُ ٱلنَّاسُ فَـَٔاوَىٰكُمْ وَأَيَّدَكُم بِنَصْرِهِۦ وَرَزَقَكُم مِّنَ ٱلطَّيِّبَـٰتِ لَعَلَّكُمْ تَشْكُرُونَ
Transliteration wa-udh'kurū idh antum qalīlun mus'taḍʿafūna fī l-arḍi takhāfūna an yatakhaṭṭafakumu l-nāsu faāwākum wa-ayyadakum binaṣrihi warazaqakum mina l-ṭayibāti laʿallakum tashkurūna
Yoruba Ẹ rántí pé nígbà tí ẹ̀yin kéré ní òǹkà, tí ẹ wà ní ipò ọ̀lẹ (lábẹ́ wọn) lórí ilẹ̀ (ìyẹn nínú ìlú Mọkkah), ẹ sì ń páyà pé àwọn ènìyàn máa ji yín gbé lọ, nígbà náà (Allāhu) ṣe ibùgbé fún yín (nínú ìlú Mọdīnah Onímọ̀ọ́lẹ̀), Ó sì fi àrànṣe Rẹ ṣe ìkúnlọ́wọ́ fún yín. Ó tún pèsè fún yín nínú àwọn n̄ǹkan dáadáa nítorí kí ẹ lè dúpẹ́.
Verse 27
يَـٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُوا۟ لَا تَخُونُوا۟ ٱللَّهَ وَٱلرَّسُولَ وَتَخُونُوٓا۟ أَمَـٰنَـٰتِكُمْ وَأَنتُمْ تَعْلَمُونَ
Transliteration yāayyuhā alladhīna āmanū lā takhūnū l-laha wal-rasūla watakhūnū amānātikum wa-antum taʿlamūna
Yoruba Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ má ṣe jàǹbá (ọ̀ran-anyàn) Allāhu àti (sunnah) Òjíṣẹ́; ẹ má ṣe jàǹbá àwọn àgbàfipamọ́ yín, ẹ sì mọ (ìjàǹbá).
Verse 28
وَٱعْلَمُوٓا۟ أَنَّمَآ أَمْوَٰلُكُمْ وَأَوْلَـٰدُكُمْ فِتْنَةٌ وَأَنَّ ٱللَّهَ عِندَهُۥٓ أَجْرٌ عَظِيمٌ
Transliteration wa-iʿ'lamū annamā amwālukum wa-awlādukum fit'natun wa-anna l-laha ʿindahu ajrun ʿaẓīmun
Yoruba Kí ẹ sì mọ̀ pé dájúdájú ìfòòró ni àwọn dúkìá yín àti àwọn ọmọ yín, àti pé dájúdájú Allāhu ni ẹ̀san ńlá wà ní ọ̀dọ̀ Rẹ̀.
Verse 29
يَـٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُوٓا۟ إِن تَتَّقُوا۟ ٱللَّهَ يَجْعَل لَّكُمْ فُرْقَانًا وَيُكَفِّرْ عَنكُمْ سَيِّـَٔاتِكُمْ وَيَغْفِرْ لَكُمْ ۗ وَٱللَّهُ ذُو ٱلْفَضْلِ ٱلْعَظِيمِ
Transliteration yāayyuhā alladhīna āmanū in tattaqū l-laha yajʿal lakum fur'qānan wayukaffir ʿankum sayyiātikum wayaghfir lakum wal-lahu dhū l-faḍli l-ʿaẓīmi
Yoruba Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, tí ẹ bá bẹ̀rù Allāhu, Ó máa fún yín ní ọ̀nà àbáyọ. Ó máa pa àwọn àṣìṣe yín rẹ́ fún yín. Ó sì máa foríjìn yín. Allāhu sì ni Ọlọ́lá tó tóbi.
Verse 30
وَإِذْ يَمْكُرُ بِكَ ٱلَّذِينَ كَفَرُوا۟ لِيُثْبِتُوكَ أَوْ يَقْتُلُوكَ أَوْ يُخْرِجُوكَ ۚ وَيَمْكُرُونَ وَيَمْكُرُ ٱللَّهُ ۖ وَٱللَّهُ خَيْرُ ٱلْمَـٰكِرِينَ
Transliteration wa-idh yamkuru bika alladhīna kafarū liyuth'bitūka aw yaqtulūka aw yukh'rijūka wayamkurūna wayamkuru l-lahu wal-lahu khayru l-mākirīna
Yoruba (Rántí) nígbà tí àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ ń déte sí ọ láti dè ọ́ mọ́lẹ̀ tàbí láti pa ọ́ tàbí láti yọ ọ́ kúrò nínú ìlú; wọ́n ń déte, Allāhu sì ń déte. Allāhu sì lóore jùlọ nínú àwọn adéte.1
Verse 31
وَإِذَا تُتْلَىٰ عَلَيْهِمْ ءَايَـٰتُنَا قَالُوا۟ قَدْ سَمِعْنَا لَوْ نَشَآءُ لَقُلْنَا مِثْلَ هَـٰذَآ ۙ إِنْ هَـٰذَآ إِلَّآ أَسَـٰطِيرُ ٱلْأَوَّلِينَ
Transliteration wa-idhā tut'lā ʿalayhim āyātunā qālū qad samiʿ'nā law nashāu laqul'nā mith'la hādhā in hādhā illā asāṭīru l-awalīna
Yoruba Nígbà tí A bá ń ké àwọn āyah Wa fún wọn, wọ́n á wí pé: “A kúkú ti gbọ́. Tí ó bá jẹ́ pé a bá fẹ́ ni. àwa náà ìbá sọ irú èyí. Kí ni èyí bí kò ṣe àkọsílẹ̀ àlọ́ àwọn ẹni àkọ́kọ́.”
Verse 32
وَإِذْ قَالُوا۟ ٱللَّهُمَّ إِن كَانَ هَـٰذَا هُوَ ٱلْحَقَّ مِنْ عِندِكَ فَأَمْطِرْ عَلَيْنَا حِجَارَةً مِّنَ ٱلسَّمَآءِ أَوِ ٱئْتِنَا بِعَذَابٍ أَلِيمٍ
Transliteration wa-idh qālū l-lahuma in kāna hādhā huwa l-ḥaqa min ʿindika fa-amṭir ʿalaynā ḥijāratan mina l-samāi awi i'tinā biʿadhābin alīmin
Yoruba (Rántí) nígbà tí wọ́n wí pé: “Allāhu, tí ó bá jẹ́ pé èyí ni òdodo láti ọ̀dọ̀ Rẹ, rọ òjò òkúta lé wa lórí láti sánmọ̀ tàbí kí O mú ìyà ẹlẹ́ta-eléro kan wá bá wa.”
Verse 33
وَمَا كَانَ ٱللَّهُ لِيُعَذِّبَهُمْ وَأَنتَ فِيهِمْ ۚ وَمَا كَانَ ٱللَّهُ مُعَذِّبَهُمْ وَهُمْ يَسْتَغْفِرُونَ
Transliteration wamā kāna l-lahu liyuʿadhibahum wa-anta fīhim wamā kāna l-lahu muʿadhibahum wahum yastaghfirūna
Yoruba Allāhu kò níí jẹ wọ́n níyà nígbà tí ìwọ sì ń bẹ láààrin wọn. Allāhu kò sì níí jẹ wọ́n níyà nígbà tí wọ́n sì ń tọrọ àforíjìn.
Verse 34
وَمَا لَهُمْ أَلَّا يُعَذِّبَهُمُ ٱللَّهُ وَهُمْ يَصُدُّونَ عَنِ ٱلْمَسْجِدِ ٱلْحَرَامِ وَمَا كَانُوٓا۟ أَوْلِيَآءَهُۥٓ ۚ إِنْ أَوْلِيَآؤُهُۥٓ إِلَّا ٱلْمُتَّقُونَ وَلَـٰكِنَّ أَكْثَرَهُمْ لَا يَعْلَمُونَ
Transliteration wamā lahum allā yuʿadhibahumu l-lahu wahum yaṣuddūna ʿani l-masjidi l-ḥarāmi wamā kānū awliyāahu in awliyāuhu illā l-mutaqūna walākinna aktharahum lā yaʿlamūna
Yoruba Kò sí ìdí tí Allāhu kò fi níí jẹ wọ́n níyà níwọ̀n ìgbà tí wọ́n bá ń ṣẹ́ àwọn ènìyàn lórí kúrò nínú Mọ́sálásí Haram. Àti pé àwọn ọ̀ṣẹbọ kọ́ ni alámòjúútó rẹ̀. Kò sí alámòjúútó kan fún un bí kò ṣe àwọn olùbẹ̀rù (Allāhu), ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn ni kò mọ̀.
Verse 35
وَمَا كَانَ صَلَاتُهُمْ عِندَ ٱلْبَيْتِ إِلَّا مُكَآءً وَتَصْدِيَةً ۚ فَذُوقُوا۟ ٱلْعَذَابَ بِمَا كُنتُمْ تَكْفُرُونَ
Transliteration wamā kāna ṣalātuhum ʿinda l-bayti illā mukāan wataṣdiyatan fadhūqū l-ʿadhāba bimā kuntum takfurūna
Yoruba Ìjọ́sìn àwọn ọ̀ṣẹbọ ní Ilé (Kaabah) kò sì tayọ ṣíṣú ìfé àti pípa àtẹ́wọ́. Nítorí náà, ẹ tọ́ Ìyà wò nítorí pé ẹ jẹ́ aláìgbàgbọ́.
Verse 36
إِنَّ ٱلَّذِينَ كَفَرُوا۟ يُنفِقُونَ أَمْوَٰلَهُمْ لِيَصُدُّوا۟ عَن سَبِيلِ ٱللَّهِ ۚ فَسَيُنفِقُونَهَا ثُمَّ تَكُونُ عَلَيْهِمْ حَسْرَةً ثُمَّ يُغْلَبُونَ ۗ وَٱلَّذِينَ كَفَرُوٓا۟ إِلَىٰ جَهَنَّمَ يُحْشَرُونَ
Transliteration inna alladhīna kafarū yunfiqūna amwālahum liyaṣuddū ʿan sabīli l-lahi fasayunfiqūnahā thumma takūnu ʿalayhim ḥasratan thumma yugh'labūna wa-alladhīna kafarū ilā jahannama yuḥ'sharūna
Yoruba Dájúdájú àwọn tó ṣàì gbàgbọ́, wọ́n ń ná dúkìá wọn nítorí kí wọ́n lè ṣẹ́rí àwọn ènìyàn kúrò lójú ọ̀nà (ẹ̀sìn) Allāhu. Wọ́n sì ń ná a lọ (bẹ́ẹ̀). Lẹ́yìn náà, ó máa di àbámọ̀ fún wọn. Lẹ́yìn náà, A sì máa borí wọn. Àti pé àwọn tó ṣàì gbàgbọ́, inú iná Jahanamọ ni A máa kó wọn jọ sí
Verse 37
لِيَمِيزَ ٱللَّهُ ٱلْخَبِيثَ مِنَ ٱلطَّيِّبِ وَيَجْعَلَ ٱلْخَبِيثَ بَعْضَهُۥ عَلَىٰ بَعْضٍ فَيَرْكُمَهُۥ جَمِيعًا فَيَجْعَلَهُۥ فِى جَهَنَّمَ ۚ أُو۟لَـٰٓئِكَ هُمُ ٱلْخَـٰسِرُونَ
Transliteration liyamīza l-lahu l-khabītha mina l-ṭayibi wayajʿala l-khabītha baʿḍahu ʿalā baʿḍin fayarkumahu jamīʿan fayajʿalahu fī jahannama ulāika humu l-khāsirūna
Yoruba nítorí kí Allāhu lè ya àwọn ẹni ibi sọ́tọ̀ kúrò lára àwọn ẹni ire àti nítorí kí Ó lè kó àwọn ẹni ibi papọ̀; apá kan wọn mọ́ apá kan, kí Ó sì lè rọ́ gbogbo wọn papọ̀ pátápátá (sójú kan náà), Ó sì máa fi wọ́n sínú iná Jahanamọ. Àwọn wọ̀nyẹn gan-an ni ẹni òfò.
Verse 38
قُل لِّلَّذِينَ كَفَرُوٓا۟ إِن يَنتَهُوا۟ يُغْفَرْ لَهُم مَّا قَدْ سَلَفَ وَإِن يَعُودُوا۟ فَقَدْ مَضَتْ سُنَّتُ ٱلْأَوَّلِينَ
Transliteration qul lilladhīna kafarū in yantahū yugh'far lahum mā qad salafa wa-in yaʿūdū faqad maḍat sunnatu l-awalīna
Yoruba Sọ fún àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ pé tí wọ́n bá jáwọ́ (nínú àìgbàgbọ́), A máa ṣàforíjìn ohun tó ti ré kọjá fún wọn. Tí wọ́n bá tún padà (síbẹ̀, àpèjúwe) ìparun àwọn ẹni àkọ́kọ́ kúkú ti ré kọjá (ní ìkìlọ̀ fún wọn).
Verse 39
وَقَـٰتِلُوهُمْ حَتَّىٰ لَا تَكُونَ فِتْنَةٌ وَيَكُونَ ٱلدِّينُ كُلُّهُۥ لِلَّهِ ۚ فَإِنِ ٱنتَهَوْا۟ فَإِنَّ ٱللَّهَ بِمَا يَعْمَلُونَ بَصِيرٌ
Transliteration waqātilūhum ḥattā lā takūna fit'natun wayakūna l-dīnu kulluhu lillahi fa-ini intahaw fa-inna l-laha bimā yaʿmalūna baṣīrun
Yoruba Ẹ jà wọ́n lógun títí kò fi níí sí ìfòòró (ìbọ̀rìṣà) mọ́, gbogbo ẹ̀sìn yó sì lè jẹ́ ti Allāhu pátápátá. Nítorí náà, tí wọ́n bá jáwọ́ (nínú àìgbàgbọ́), dájúdájú Allāhu ni Olùríran nípa ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́.
Verse 40
وَإِن تَوَلَّوْا۟ فَٱعْلَمُوٓا۟ أَنَّ ٱللَّهَ مَوْلَىٰكُمْ ۚ نِعْمَ ٱلْمَوْلَىٰ وَنِعْمَ ٱلنَّصِيرُ
Transliteration wa-in tawallaw fa-iʿ'lamū anna l-laha mawlākum niʿ'ma l-mawlā waniʿ'ma l-naṣīru
Yoruba Tí wọ́n bá sì gbúnrí (kúrò nínú ìgbàgbọ́), ẹ mọ̀ pé dájúdájú Allāhu ni Aláfẹ̀yìntì yín. Ó dára ní Aláfẹ̀yìntì. Ó sì dára ní Alárànṣe.
Verse 41
۞ وَٱعْلَمُوٓا۟ أَنَّمَا غَنِمْتُم مِّن شَىْءٍ فَأَنَّ لِلَّهِ خُمُسَهُۥ وَلِلرَّسُولِ وَلِذِى ٱلْقُرْبَىٰ وَٱلْيَتَـٰمَىٰ وَٱلْمَسَـٰكِينِ وَٱبْنِ ٱلسَّبِيلِ إِن كُنتُمْ ءَامَنتُم بِٱللَّهِ وَمَآ أَنزَلْنَا عَلَىٰ عَبْدِنَا يَوْمَ ٱلْفُرْقَانِ يَوْمَ ٱلْتَقَى ٱلْجَمْعَانِ ۗ وَٱللَّهُ عَلَىٰ كُلِّ شَىْءٍ قَدِيرٌ
Transliteration wa-iʿ'lamū annamā ghanim'tum min shayin fa-anna lillahi khumusahu walilrrasūli walidhī l-qur'bā wal-yatāmā wal-masākīni wa-ib'ni l-sabīli in kuntum āmantum bil-lahi wamā anzalnā ʿalā ʿabdinā yawma l-fur'qāni yawma l-taqā l-jamʿāni wal-lahu ʿalā kulli shayin qadīrun
Yoruba Ẹ mọ̀ pé ohunkóhun tí ẹ bá kó ní ọrọ̀ ogun, dájúdájú ti Allāhu ni ìdá márùn-ún rẹ̀. Ó sì wà fún Òjíṣẹ́ àti ẹbí (rẹ̀) àti àwọn ọmọ òrukàn, àwọn mẹ̀kúnnù àti onírìn-àjò (tí agara dá), tí ẹ bá jẹ́ ẹni tó gbàgbọ́ nínú Allāhu àti n̄ǹkan tí A sọ̀kalẹ̀ fún ẹrúsìn Wa ní Ọjọ́ ìpínyà, ọjọ́ tí ìjọ méjì pàdé (lójú ogun Badr). Allāhu sì ni Alágbára lórí gbogbo n̄ǹkan.
Verse 42
إِذْ أَنتُم بِٱلْعُدْوَةِ ٱلدُّنْيَا وَهُم بِٱلْعُدْوَةِ ٱلْقُصْوَىٰ وَٱلرَّكْبُ أَسْفَلَ مِنكُمْ ۚ وَلَوْ تَوَاعَدتُّمْ لَٱخْتَلَفْتُمْ فِى ٱلْمِيعَـٰدِ ۙ وَلَـٰكِن لِّيَقْضِىَ ٱللَّهُ أَمْرًا كَانَ مَفْعُولًا لِّيَهْلِكَ مَنْ هَلَكَ عَنۢ بَيِّنَةٍ وَيَحْيَىٰ مَنْ حَىَّ عَنۢ بَيِّنَةٍ ۗ وَإِنَّ ٱللَّهَ لَسَمِيعٌ عَلِيمٌ
Transliteration idh antum bil-ʿud'wati l-dun'yā wahum bil-ʿud'wati l-quṣ'wā wal-rakbu asfala minkum walaw tawāʿadttum la-ikh'talaftum fī l-mīʿādi walākin liyaqḍiya l-lahu amran kāna mafʿūlan liyahlika man halaka ʿan bayyinatin wayaḥyā man ḥayya ʿan bayyinatin wa-inna l-laha lasamīʿun ʿalīmun
Yoruba (Ẹ rántí) nígbà tí ẹ̀yin wà ní etí kòtò tó súnmọ́ (ìlú Mọdīnah), àwọn (kèfèrí) sì wà ní etí kòtò tó jìnnà sí (ìlú Mọdīnah), àwọn kèfèrí kan tó ń gun n̄ǹkan ìgùn (bọ̀ láti ìrìn-àjò òkòwò), wọ́n sì wà ní ìsàlẹ̀ ọ̀dọ̀ tiyín. Tí ó bá jẹ́ pé ẹ̀yin àti àwọn kèfèrí jọ mú ọjọ́ fún ogun náà ni, ẹ̀yin ìbá yapa àdéhùn náà, ṣùgbọ́n (ogun náà ṣẹlẹ̀ bẹ́ẹ̀) nítorí kí Allāhu lè mú ọ̀rọ̀ kan tí ó gbọ́dọ̀ ṣẹ wá sí ìmúṣẹ; nítorí kí ẹni tí ó máa parun (sínú àìgbàgbọ́) lè parun nípasẹ̀ ẹ̀rí tó yanjú, kí ẹni tó sì máa yè (nínú ìgbàgbọ́ òdodo) lè yè nípasẹ̀ ẹ̀rí tó yanjú. Àti pé dájúdájú Allāhu kúkú ni Olùgbọ́, Onímọ̀.
Verse 43
إِذْ يُرِيكَهُمُ ٱللَّهُ فِى مَنَامِكَ قَلِيلًا ۖ وَلَوْ أَرَىٰكَهُمْ كَثِيرًا لَّفَشِلْتُمْ وَلَتَنَـٰزَعْتُمْ فِى ٱلْأَمْرِ وَلَـٰكِنَّ ٱللَّهَ سَلَّمَ ۗ إِنَّهُۥ عَلِيمٌۢ بِذَاتِ ٱلصُّدُورِ
Transliteration idh yurīkahumu l-lahu fī manāmika qalīlan walaw arākahum kathīran lafashil'tum walatanāzaʿtum fī l-amri walākinna l-laha sallama innahu ʿalīmun bidhāti l-ṣudūri
Yoruba (Rántí) nígbà tí Allāhu fi wọ́n hàn ọ́ nínú àlá rẹ (pé wọ́n) kéré. Tí ó bá jẹ́ pé Ó fi wọ́n hàn ọ́ (pé wọ́n) pọ̀ ni, ẹ̀yin ìbá ṣojo, ẹ̀yin ìbá sì ṣàríyànjiyàn nípa ọ̀rọ̀ náà. Ṣùgbọ́n Allāhu ko (yín) yọ. Dájúdájú Òun ni Onímọ̀ nípa n̄ǹkan tí ń bẹ nínú igbá-àyà ẹ̀dá.
Verse 44
وَإِذْ يُرِيكُمُوهُمْ إِذِ ٱلْتَقَيْتُمْ فِىٓ أَعْيُنِكُمْ قَلِيلًا وَيُقَلِّلُكُمْ فِىٓ أَعْيُنِهِمْ لِيَقْضِىَ ٱللَّهُ أَمْرًا كَانَ مَفْعُولًا ۗ وَإِلَى ٱللَّهِ تُرْجَعُ ٱلْأُمُورُ
Transliteration wa-idh yurīkumūhum idhi l-taqaytum fī aʿyunikum qalīlan wayuqallilukum fī aʿyunihim liyaqḍiya l-lahu amran kāna mafʿūlan wa-ilā l-lahi tur'jaʿu l-umūru
Yoruba (Rántí) nígbà tí Ó ń fi wọ́n hàn yín pé wọ́n kéré lójú yín - nígbà tí ẹ pàdé (lójú ogun) - Ó sì mú ẹ̀yin náà kéré lójú tiwọn náà, nítorí kí Allāhu lè mú ọ̀rọ̀ kan tí ó gbọ́dọ̀ ṣẹ wá sí ìmúṣẹ. Ọ̀dọ̀ Allāhu sì ni wọ́n máa ṣẹ́rí àwọn ọ̀rọ̀ ẹ̀dá padà sí.
Verse 45
يَـٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُوٓا۟ إِذَا لَقِيتُمْ فِئَةً فَٱثْبُتُوا۟ وَٱذْكُرُوا۟ ٱللَّهَ كَثِيرًا لَّعَلَّكُمْ تُفْلِحُونَ
Transliteration yāayyuhā alladhīna āmanū idhā laqītum fi-atan fa-uth'butū wa-udh'kurū l-laha kathīran laʿallakum tuf'liḥūna
Yoruba Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, nígbà tí ẹ bá pàdé ìjọ (ogun) kan, ẹ dúró ṣinṣin, kí ẹ sì ṣe (gbólóhùn) ìrántí Allāhu ní (òǹkà) púpọ̀ nítorí kí ẹ lè jèrè.
Verse 46
وَأَطِيعُوا۟ ٱللَّهَ وَرَسُولَهُۥ وَلَا تَنَـٰزَعُوا۟ فَتَفْشَلُوا۟ وَتَذْهَبَ رِيحُكُمْ ۖ وَٱصْبِرُوٓا۟ ۚ إِنَّ ٱللَّهَ مَعَ ٱلصَّـٰبِرِينَ
Transliteration wa-aṭīʿū l-laha warasūlahu walā tanāzaʿū fatafshalū watadhhaba rīḥukum wa-iṣ'birū inna l-laha maʿa l-ṣābirīna
Yoruba Ẹ tẹ̀lé ti Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀. Ẹ má ṣe jara yín níyàn (nípa ogun ẹ̀sìn) nítorí kí ẹ má baà ṣojo àti nítorí kí agbára yín má baà kúrò lọ́wọ́ yín. Ẹ ṣe sùúrù, dájúdájú Allāhu wà pẹ̀lú àwọn onísùúrù.
Verse 47
وَلَا تَكُونُوا۟ كَٱلَّذِينَ خَرَجُوا۟ مِن دِيَـٰرِهِم بَطَرًا وَرِئَآءَ ٱلنَّاسِ وَيَصُدُّونَ عَن سَبِيلِ ٱللَّهِ ۚ وَٱللَّهُ بِمَا يَعْمَلُونَ مُحِيطٌ
Transliteration walā takūnū ka-alladhīna kharajū min diyārihim baṭaran wariāa l-nāsi wayaṣuddūna ʿan sabīli l-lahi wal-lahu bimā yaʿmalūna muḥīṭun
Yoruba Ẹ má ṣe dà bí àwọn tó jáde kúrò nínú ilé wọn pẹ̀lú fáààrí àti ṣekárími. Wọ́n sì ń ṣẹ́rí àwọn ènìyàn kúrò lójú ọ̀nà (ẹ̀sìn) Allāhu. Allāhu sì ni Alámọ̀tán nípa ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́.
Verse 48
وَإِذْ زَيَّنَ لَهُمُ ٱلشَّيْطَـٰنُ أَعْمَـٰلَهُمْ وَقَالَ لَا غَالِبَ لَكُمُ ٱلْيَوْمَ مِنَ ٱلنَّاسِ وَإِنِّى جَارٌ لَّكُمْ ۖ فَلَمَّا تَرَآءَتِ ٱلْفِئَتَانِ نَكَصَ عَلَىٰ عَقِبَيْهِ وَقَالَ إِنِّى بَرِىٓءٌ مِّنكُمْ إِنِّىٓ أَرَىٰ مَا لَا تَرَوْنَ إِنِّىٓ أَخَافُ ٱللَّهَ ۚ وَٱللَّهُ شَدِيدُ ٱلْعِقَابِ
Transliteration wa-idh zayyana lahumu l-shayṭānu aʿmālahum waqāla lā ghāliba lakumu l-yawma mina l-nāsi wa-innī jārun lakum falammā tarāati l-fi-atāni nakaṣa ʿalā ʿaqibayhi waqāla innī barīon minkum innī arā mā lā tarawna innī akhāfu l-laha wal-lahu shadīdu l-ʿiqābi
Yoruba (Rántí) nígbà tí Èṣù ṣe iṣẹ́ wọn ní ọ̀ṣọ́ fún wọn, ó sì wí pé: “Kò sí ẹni tí ó máa borí yín lónìí nínú àwọn ènìyàn. Dájúdájú èmi ni alárànṣe yín.” Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn ìjọ ogun méjèèjì fojú kanra wọn, ó padà sẹ́yìn, ó fẹsẹ̀ fẹ́ẹ, ó wí pé: “Dájúdájú èmi ti yọwọ́-yọsẹ̀ nínú ọ̀rọ̀ yín. Dájúdájú èmi ń rí ohun tí ẹ̀yin kò rí. Èmi ń pàyà Allāhu. Allāhu sì le níbi ìyà.”
Verse 49
إِذْ يَقُولُ ٱلْمُنَـٰفِقُونَ وَٱلَّذِينَ فِى قُلُوبِهِم مَّرَضٌ غَرَّ هَـٰٓؤُلَآءِ دِينُهُمْ ۗ وَمَن يَتَوَكَّلْ عَلَى ٱللَّهِ فَإِنَّ ٱللَّهَ عَزِيزٌ حَكِيمٌ
Transliteration idh yaqūlu l-munāfiqūna wa-alladhīna fī qulūbihim maraḍun gharra hāulāi dīnuhum waman yatawakkal ʿalā l-lahi fa-inna l-laha ʿazīzun ḥakīmun
Yoruba (Rántí) nígbà tí àwọn ṣọ̀bẹ-ṣèlu mùsùlùmí àti àwọn tí àrùn ń bẹ nínú ọkàn wọn wí pé: “Ẹ̀sìn àwọn wọ̀nyí tàn wọ́n jẹ.” Ẹnikẹ́ni tó bá gbáralé Allāhu, dájúdájú Allāhu ni Alágbára, Ọlọ́gbọ́n.
Verse 50
وَلَوْ تَرَىٰٓ إِذْ يَتَوَفَّى ٱلَّذِينَ كَفَرُوا۟ ۙ ٱلْمَلَـٰٓئِكَةُ يَضْرِبُونَ وُجُوهَهُمْ وَأَدْبَـٰرَهُمْ وَذُوقُوا۟ عَذَابَ ٱلْحَرِيقِ
Transliteration walaw tarā idh yatawaffā alladhīna kafarū l-malāikatu yaḍribūna wujūhahum wa-adbārahum wadhūqū ʿadhāba l-ḥarīqi
Yoruba Tí ó bá jẹ́ pé ìwọ rí i nígbà tí àwọn mọlāika bá ń gba ẹ̀mí àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ ni, tí wọ́n ń lu ojú wọn àti ẹ̀yìn wọn, (wọ́n sì máa sọ fún wọn pé), “Ẹ tọ́ ìyà Iná jónijóni wò.”
Verse 51
ذَٰلِكَ بِمَا قَدَّمَتْ أَيْدِيكُمْ وَأَنَّ ٱللَّهَ لَيْسَ بِظَلَّـٰمٍ لِّلْعَبِيدِ
Transliteration dhālika bimā qaddamat aydīkum wa-anna l-laha laysa biẓallāmin lil'ʿabīdi
Yoruba Ìyẹn nítorí ohun tí ọwọ́ yín tì ṣíwájú. Àti pé dájúdájú Allāhu kò níí ṣe àbòsí fún àwọn ẹrú (Rẹ̀).
Verse 52
كَدَأْبِ ءَالِ فِرْعَوْنَ ۙ وَٱلَّذِينَ مِن قَبْلِهِمْ ۚ كَفَرُوا۟ بِـَٔايَـٰتِ ٱللَّهِ فَأَخَذَهُمُ ٱللَّهُ بِذُنُوبِهِمْ ۗ إِنَّ ٱللَّهَ قَوِىٌّ شَدِيدُ ٱلْعِقَابِ
Transliteration kadabi āli fir'ʿawna wa-alladhīna min qablihim kafarū biāyāti l-lahi fa-akhadhahumu l-lahu bidhunūbihim inna l-laha qawiyyun shadīdu l-ʿiqābi
Yoruba (Ìṣesí àwọn aláìgbàgbọ́) dà bí ìṣesí àwọn ènìyàn Fir‘aon àti àwọn tó ṣíwájú wọn - wọ́n ṣàì gbàgbọ́ nínú àwọn āyah Allāhu. - Nítorí náà, Allāhu mú wọn nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Dájúdájú Allāhu ni Alágbára, Ó le níbi ìyà.
Verse 53
ذَٰلِكَ بِأَنَّ ٱللَّهَ لَمْ يَكُ مُغَيِّرًا نِّعْمَةً أَنْعَمَهَا عَلَىٰ قَوْمٍ حَتَّىٰ يُغَيِّرُوا۟ مَا بِأَنفُسِهِمْ ۙ وَأَنَّ ٱللَّهَ سَمِيعٌ عَلِيمٌ
Transliteration dhālika bi-anna l-laha lam yaku mughayyiran niʿ'matan anʿamahā ʿalā qawmin ḥattā yughayyirū mā bi-anfusihim wa-anna l-laha samīʿun ʿalīmun
Yoruba Ìyẹn nítorí pé dájúdájú Allāhu kò níí ṣe ìyípadà ìdẹ̀ra tí Ó ṣe fún ìjọ kan títí wọn yóò fi ṣe ìyípadà n̄ǹkan tí ń bẹ lọ́dọ̀ ara wọn. Dájúdájú Allāhu sì ni Olùgbọ́, Onímọ̀.
Verse 54
كَدَأْبِ ءَالِ فِرْعَوْنَ ۙ وَٱلَّذِينَ مِن قَبْلِهِمْ ۚ كَذَّبُوا۟ بِـَٔايَـٰتِ رَبِّهِمْ فَأَهْلَكْنَـٰهُم بِذُنُوبِهِمْ وَأَغْرَقْنَآ ءَالَ فِرْعَوْنَ ۚ وَكُلٌّ كَانُوا۟ ظَـٰلِمِينَ
Transliteration kadabi āli fir'ʿawna wa-alladhīna min qablihim kadhabū biāyāti rabbihim fa-ahlaknāhum bidhunūbihim wa-aghraqnā āla fir'ʿawna wakullun kānū ẓālimīna
Yoruba (Ìṣesí àwọn aláìmoore) dà bí ìṣesí àwọn ènìyàn Fir‘aon àti àwọn tó ṣíwájú wọn, tí wọ́n pe àwọn āyah Olúwa wọn nírọ́. Nítorí náà, A pa wọ́n run nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn; A sì tẹ àwọn ènìyàn Fir‘aon rì sínú agbami. Gbogbo wọn sì jẹ́ alábòsí.
Verse 55
إِنَّ شَرَّ ٱلدَّوَآبِّ عِندَ ٱللَّهِ ٱلَّذِينَ كَفَرُوا۟ فَهُمْ لَا يُؤْمِنُونَ
Transliteration inna sharra l-dawābi ʿinda l-lahi alladhīna kafarū fahum lā yu'minūna
Yoruba Dájúdájú ẹ̀dá abẹ̀mí tó burú jùlọ lọ́dọ̀ Allāhu ni àwọn tó ṣàì gbàgbọ́. Nítorí náà, wọn kò níí gbàgbọ́.
Verse 56
ٱلَّذِينَ عَـٰهَدتَّ مِنْهُمْ ثُمَّ يَنقُضُونَ عَهْدَهُمْ فِى كُلِّ مَرَّةٍ وَهُمْ لَا يَتَّقُونَ
Transliteration alladhīna ʿāhadtta min'hum thumma yanquḍūna ʿahdahum fī kulli marratin wahum lā yattaqūna
Yoruba Àwọn tí o bá ṣe àdéhùn nínú wọn, lẹ́yìn náà tí wọ́n ń tú àdéhùn wọn ní gbogbo ìgbà, tí wọn kò sì bẹ̀rù (Allāhu),
Verse 57
فَإِمَّا تَثْقَفَنَّهُمْ فِى ٱلْحَرْبِ فَشَرِّدْ بِهِم مَّنْ خَلْفَهُمْ لَعَلَّهُمْ يَذَّكَّرُونَ
Transliteration fa-immā tathqafannahum fī l-ḥarbi fasharrid bihim man khalfahum laʿallahum yadhakkarūna
Yoruba yálà tí ọwọ́ yín bá bà wọ́n lójú ogun, (ẹ pa wọ́n) kí ẹ sì (fi ogun) tú àwọn ọmọlẹ́yìn wọn ká nítorí kí wọ́n lè lo ìrántí;
Verse 58
وَإِمَّا تَخَافَنَّ مِن قَوْمٍ خِيَانَةً فَٱنۢبِذْ إِلَيْهِمْ عَلَىٰ سَوَآءٍ ۚ إِنَّ ٱللَّهَ لَا يُحِبُّ ٱلْخَآئِنِينَ
Transliteration wa-immā takhāfanna min qawmin khiyānatan fa-inbidh ilayhim ʿalā sawāin inna l-laha lā yuḥibbu l-khāinīna
Yoruba tàbí tí o bá sì ń páyà ìwà ìjàǹbá láti ọ̀dọ̀ ìjọ kan, ju àdéhùn wọn sílẹ̀ fún wọn kí ẹ dì jọ mọ̀ pé kò sí àdéhùn kan kan mọ́ láààrin ẹ̀yin méjèèjì. Dájúdájú Allāhu kò nífẹ̀ẹ́ àwọn oníjàǹbá.
Verse 59
وَلَا يَحْسَبَنَّ ٱلَّذِينَ كَفَرُوا۟ سَبَقُوٓا۟ ۚ إِنَّهُمْ لَا يُعْجِزُونَ
Transliteration walā yaḥsabanna alladhīna kafarū sabaqū innahum lā yuʿ'jizūna
Yoruba Kí àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ má ṣe lérò pé àwọn ti gbawájú. Dájúdájú wọn kò lè mórí bọ́ (nínú ìyà).
Verse 60
وَأَعِدُّوا۟ لَهُم مَّا ٱسْتَطَعْتُم مِّن قُوَّةٍ وَمِن رِّبَاطِ ٱلْخَيْلِ تُرْهِبُونَ بِهِۦ عَدُوَّ ٱللَّهِ وَعَدُوَّكُمْ وَءَاخَرِينَ مِن دُونِهِمْ لَا تَعْلَمُونَهُمُ ٱللَّهُ يَعْلَمُهُمْ ۚ وَمَا تُنفِقُوا۟ مِن شَىْءٍ فِى سَبِيلِ ٱللَّهِ يُوَفَّ إِلَيْكُمْ وَأَنتُمْ لَا تُظْلَمُونَ
Transliteration wa-aʿiddū lahum mā is'taṭaʿtum min quwwatin wamin ribāṭi l-khayli tur'hibūna bihi ʿaduwwa l-lahi waʿaduwwakum waākharīna min dūnihim lā taʿlamūnahumu l-lahu yaʿlamuhum wamā tunfiqū min shayin fī sabīli l-lahi yuwaffa ilaykum wa-antum lā tuẓ'lamūna
Yoruba Ẹ pèsè sílẹ̀ dè wọ́n n̄ǹkan ìjà tí agbára yín ká nínú n̄ǹkan àmúṣagbára àti àwọn ẹṣin orí ìso, tí ẹ̀yin yóò fi máa dẹ́rù ba ọ̀tá Allāhu àti ọ̀tá yín pẹ̀lú àwọn mìíràn yàtọ̀ sí wọn, tí ẹ̀yin kò mọ̀ wọ́n – Allāhu sì mọ̀ wọ́n. – Ohunkóhun tí ẹ bá ná lójú ọ̀nà (ẹ̀sìn) Allāhu, A óò san án padà fún yín ní kíkún; A ò sì níí ṣe àbòsí fún yín.
Verse 61
۞ وَإِن جَنَحُوا۟ لِلسَّلْمِ فَٱجْنَحْ لَهَا وَتَوَكَّلْ عَلَى ٱللَّهِ ۚ إِنَّهُۥ هُوَ ٱلسَّمِيعُ ٱلْعَلِيمُ
Transliteration wa-in janaḥū lilssalmi fa-ij'naḥ lahā watawakkal ʿalā l-lahi innahu huwa l-samīʿu l-ʿalīmu
Yoruba Tí wọ́n bá tẹ̀ síbi (ètò) àlàáfíà (fún dídá ogun dúró), ìwọ náà tẹ̀ síbẹ̀, kí o sì gbáralé Allāhu. Dájúdájú Òun mà ni Olùgbọ́, Onímọ̀.
Verse 62
وَإِن يُرِيدُوٓا۟ أَن يَخْدَعُوكَ فَإِنَّ حَسْبَكَ ٱللَّهُ ۚ هُوَ ٱلَّذِىٓ أَيَّدَكَ بِنَصْرِهِۦ وَبِٱلْمُؤْمِنِينَ
Transliteration wa-in yurīdū an yakhdaʿūka fa-inna ḥasbaka l-lahu huwa alladhī ayyadaka binaṣrihi wabil-mu'minīna
Yoruba Tí wọ́n bá tún fẹ́ tàn ọ́ jẹ, dájúdájú Allāhu á tó ọ. Òun ni Ẹni tí Ó fi àrànṣe Rẹ̀ àti àwọn onígbàgbọ́ òdodo ràn ọ́ lọ́wọ́.
Verse 63
وَأَلَّفَ بَيْنَ قُلُوبِهِمْ ۚ لَوْ أَنفَقْتَ مَا فِى ٱلْأَرْضِ جَمِيعًا مَّآ أَلَّفْتَ بَيْنَ قُلُوبِهِمْ وَلَـٰكِنَّ ٱللَّهَ أَلَّفَ بَيْنَهُمْ ۚ إِنَّهُۥ عَزِيزٌ حَكِيمٌ
Transliteration wa-allafa bayna qulūbihim law anfaqta mā fī l-arḍi jamīʿan mā allafta bayna qulūbihim walākinna l-laha allafa baynahum innahu ʿazīzun ḥakīmun
Yoruba Allāhu pa ọkàn wọn pọ̀ mọ́ra wọn. Tí ó bá jẹ́ pé o ná gbogbo n̄ǹkan tí ń bẹ lórí ilẹ̀ pátápátá, ìwọ kò lè pa ọkàn wọn pọ̀ mọ́ra wọn. Ṣùgbọ́n Allāhu pa ọkàn wọn pọ̀ mọ́ra wọn, dájúdájú Òun ni Alágbára, Ọlọ́gbọ́n.
Verse 64
يَـٰٓأَيُّهَا ٱلنَّبِىُّ حَسْبُكَ ٱللَّهُ وَمَنِ ٱتَّبَعَكَ مِنَ ٱلْمُؤْمِنِينَ
Transliteration yāayyuhā l-nabiyu ḥasbuka l-lahu wamani ittabaʿaka mina l-mu'minīna
Yoruba Ìwọ Ànábì, Allāhu ti tó ìwọ àti àwọn tó tẹ̀lé ọ nínú àwọn onígbàgbọ́ òdodo.
Verse 65
يَـٰٓأَيُّهَا ٱلنَّبِىُّ حَرِّضِ ٱلْمُؤْمِنِينَ عَلَى ٱلْقِتَالِ ۚ إِن يَكُن مِّنكُمْ عِشْرُونَ صَـٰبِرُونَ يَغْلِبُوا۟ مِا۟ئَتَيْنِ ۚ وَإِن يَكُن مِّنكُم مِّا۟ئَةٌ يَغْلِبُوٓا۟ أَلْفًا مِّنَ ٱلَّذِينَ كَفَرُوا۟ بِأَنَّهُمْ قَوْمٌ لَّا يَفْقَهُونَ
Transliteration yāayyuhā l-nabiyu ḥarriḍi l-mu'minīna ʿalā l-qitāli in yakun minkum ʿish'rūna ṣābirūna yaghlibū mi-atayni wa-in yakun minkum mi-atun yaghlibū alfan mina alladhīna kafarū bi-annahum qawmun lā yafqahūna
Yoruba Ìwọ Ànábì, gba àwọn onígbàgbọ́ òdodo ní ìyànjú lórí ogun ẹ̀sìn. Tí ogún onísùúrù bá wà nínú yín, wọn yóò borí igba. Tí ọgọ́rùn-ún bá sì wà nínú yín, wọn yóò borí ẹgbẹ̀rún nínú àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ nítorí pé dájúdájú wọ́n jẹ́ ìjọ tí kò gbọ́ àgbọ́yé.
Verse 66
ٱلْـَٔـٰنَ خَفَّفَ ٱللَّهُ عَنكُمْ وَعَلِمَ أَنَّ فِيكُمْ ضَعْفًا ۚ فَإِن يَكُن مِّنكُم مِّا۟ئَةٌ صَابِرَةٌ يَغْلِبُوا۟ مِا۟ئَتَيْنِ ۚ وَإِن يَكُن مِّنكُمْ أَلْفٌ يَغْلِبُوٓا۟ أَلْفَيْنِ بِإِذْنِ ٱللَّهِ ۗ وَٱللَّهُ مَعَ ٱلصَّـٰبِرِينَ
Transliteration al-āna khaffafa l-lahu ʿankum waʿalima anna fīkum ḍaʿfan fa-in yakun minkum mi-atun ṣābiratun yaghlibū mi-atayni wa-in yakun minkum alfun yaghlibū alfayni bi-idh'ni l-lahi wal-lahu maʿa l-ṣābirīna
Yoruba Nísisìn yìí, Allāhu ti ṣe é ní fífúyẹ́ fún yín. Ó sì mọ̀ pé dájúdájú àìlágbára ń bẹ fún yín. Nítorí náà, tí ọgọ́rùn-ún onísùúrù bá wà nínú yín, wọn yóò borí igba. Tí ẹgbẹ̀rún kan bá sì wà nínú yín, wọn yóò borí ẹgbẹ̀rún méjì pẹ̀lú àṣẹ Allāhu. Allāhu sì wà pẹ̀lú àwọn onísùúrù.
Verse 67
مَا كَانَ لِنَبِىٍّ أَن يَكُونَ لَهُۥٓ أَسْرَىٰ حَتَّىٰ يُثْخِنَ فِى ٱلْأَرْضِ ۚ تُرِيدُونَ عَرَضَ ٱلدُّنْيَا وَٱللَّهُ يُرِيدُ ٱلْـَٔاخِرَةَ ۗ وَٱللَّهُ عَزِيزٌ حَكِيمٌ
Transliteration mā kāna linabiyyin an yakūna lahu asrā ḥattā yuth'khina fī l-arḍi turīdūna ʿaraḍa l-dun'yā wal-lahu yurīdu l-ākhirata wal-lahu ʿazīzun ḥakīmun
Yoruba Kò yẹ fún Ànábì kan láti ní ẹrú ogun títí ọwọ́ rẹ̀ máa fi ba àwọn ọ̀tá rẹ̀ lórí ilẹ̀ dáadáa ní ti pípa.Ẹ̀yin ń fẹ́ ìgbádùn ayé, Allāhu sì ń fẹ́ ọ̀run. Allāhu sì ni Alágbára, Ọlọ́gbọ́n.
Verse 68
لَّوْلَا كِتَـٰبٌ مِّنَ ٱللَّهِ سَبَقَ لَمَسَّكُمْ فِيمَآ أَخَذْتُمْ عَذَابٌ عَظِيمٌ
Transliteration lawlā kitābun mina l-lahi sabaqa lamassakum fīmā akhadhtum ʿadhābun ʿaẓīmun
Yoruba Tí kì í bá ṣe ti àkọsílẹ̀ kan tó ti gbawájú láti ọ̀dọ̀ Allāhu ni, ọwọ́ ìyà ńlá kò bá tẹ̀ yín nípa n̄ǹkan tí ẹ gbà (ní owó ìtúsílẹ̀).
Verse 69
فَكُلُوا۟ مِمَّا غَنِمْتُمْ حَلَـٰلًا طَيِّبًا ۚ وَٱتَّقُوا۟ ٱللَّهَ ۚ إِنَّ ٱللَّهَ غَفُورٌ رَّحِيمٌ
Transliteration fakulū mimmā ghanim'tum ḥalālan ṭayyiban wa-ittaqū l-laha inna l-laha ghafūrun raḥīmun
Yoruba Nítorí náà, ẹ jẹ nínú ohun tí ẹ kó ní ọrọ̀ ogun (tí ó jẹ́) ẹ̀tọ́ (àti) n̄ǹkan dáadáa. Kí ẹ sì bẹ̀rù Allāhu. Dájúdájú Allāhu ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.
Verse 70
يَـٰٓأَيُّهَا ٱلنَّبِىُّ قُل لِّمَن فِىٓ أَيْدِيكُم مِّنَ ٱلْأَسْرَىٰٓ إِن يَعْلَمِ ٱللَّهُ فِى قُلُوبِكُمْ خَيْرًا يُؤْتِكُمْ خَيْرًا مِّمَّآ أُخِذَ مِنكُمْ وَيَغْفِرْ لَكُمْ ۗ وَٱللَّهُ غَفُورٌ رَّحِيمٌ
Transliteration yāayyuhā l-nabiyu qul liman fī aydīkum mina l-asrā in yaʿlami l-lahu fī qulūbikum khayran yu'tikum khayran mimmā ukhidha minkum wayaghfir lakum wal-lahu ghafūrun raḥīmun
Yoruba Ìwọ Ànábì, sọ fún àwọn tó ń bẹ lọ́wọ́ yín nínú àwọn ẹrú ogun pé, “Tí Allāhu bá mọ dáadáa kan nínú ọkàn yín, Ó máa fún yín ní ohun tó dára ju ohun tí wọ́n gbà lọ́wọ́ yín. Ó sì máa foríjìn yín. Allāhu sì ni Aláforíjìn, Oníkẹ̀ẹ́.”
Verse 71
وَإِن يُرِيدُوا۟ خِيَانَتَكَ فَقَدْ خَانُوا۟ ٱللَّهَ مِن قَبْلُ فَأَمْكَنَ مِنْهُمْ ۗ وَٱللَّهُ عَلِيمٌ حَكِيمٌ
Transliteration wa-in yurīdū khiyānataka faqad khānū l-laha min qablu fa-amkana min'hum wal-lahu ʿalīmun ḥakīmun
Yoruba Tí wọ́n bá sì ń gbèrò ìjàǹbá sí ọ, wọ́n kúkú ti jàǹbá Allāhu ṣíwájú. Ó sì fún ọ lágbára lórí wọn. Allāhu sì ni Onímọ̀, Ọlọ́gbọ́n.
Verse 72
إِنَّ ٱلَّذِينَ ءَامَنُوا۟ وَهَاجَرُوا۟ وَجَـٰهَدُوا۟ بِأَمْوَٰلِهِمْ وَأَنفُسِهِمْ فِى سَبِيلِ ٱللَّهِ وَٱلَّذِينَ ءَاوَوا۟ وَّنَصَرُوٓا۟ أُو۟لَـٰٓئِكَ بَعْضُهُمْ أَوْلِيَآءُ بَعْضٍ ۚ وَٱلَّذِينَ ءَامَنُوا۟ وَلَمْ يُهَاجِرُوا۟ مَا لَكُم مِّن وَلَـٰيَتِهِم مِّن شَىْءٍ حَتَّىٰ يُهَاجِرُوا۟ ۚ وَإِنِ ٱسْتَنصَرُوكُمْ فِى ٱلدِّينِ فَعَلَيْكُمُ ٱلنَّصْرُ إِلَّا عَلَىٰ قَوْمٍۭ بَيْنَكُمْ وَبَيْنَهُم مِّيثَـٰقٌ ۗ وَٱللَّهُ بِمَا تَعْمَلُونَ بَصِيرٌ
Transliteration inna alladhīna āmanū wahājarū wajāhadū bi-amwālihim wa-anfusihim fī sabīli l-lahi wa-alladhīna āwaw wanaṣarū ulāika baʿḍuhum awliyāu baʿḍin wa-alladhīna āmanū walam yuhājirū mā lakum min walāyatihim min shayin ḥattā yuhājirū wa-ini is'tanṣarūkum fī l-dīni faʿalaykumu l-naṣru illā ʿalā qawmin baynakum wabaynahum mīthāqun wal-lahu bimā taʿmalūna baṣīrun
Yoruba Dájúdájú àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n gbé ìlú wọn jù sílẹ̀, tí wọ́n sì fi dúkìá wọn àti ẹ̀mí wọn jagun lójú ọ̀nà (ẹ̀sìn) Allāhu, àti àwọn tó gbà wọ́n sọ́dọ̀ (nínú ìlú), tí wọ́n sì ràn wọ́n lọ́wọ́; àwọn wọ̀nyẹn, apá kan wọn l’ọ̀rẹ́ apá kan (tó lè jogún ara wọn). Àwọn tó gbàgbọ́, tí wọn kò sì gbé ìlú wọn jù sílẹ̀, kò lẹ́tọ̀ọ́ fún yín láti mú wọn lọ́rẹ̀ẹ́ níbì kan kan (tó lè mu yín jogún ara yín), títí wọn yóò fi gbé ìlú wọn jù sílẹ̀.Tí wọ́n bá sì wá ìrànlọ́wọ́ yín (lórí ọ̀tá) nípa ẹ̀sìn, ìrànlọ́wọ́ náà di dandan fún yín àyàfi lórí ìjọ kan tí àdéhùn ń bẹ láààrin ẹ̀yin àti àwọn. Allāhu sì ni Olùríran nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.
Verse 73
وَٱلَّذِينَ كَفَرُوا۟ بَعْضُهُمْ أَوْلِيَآءُ بَعْضٍ ۚ إِلَّا تَفْعَلُوهُ تَكُن فِتْنَةٌ فِى ٱلْأَرْضِ وَفَسَادٌ كَبِيرٌ
Transliteration wa-alladhīna kafarū baʿḍuhum awliyāu baʿḍin illā tafʿalūhu takun fit'natun fī l-arḍi wafasādun kabīrun
Yoruba Àwọn aláìgbàgbọ́; apá kan wọn ni alátìlẹ́yìn apá kan. Àfi kí ẹ̀yin náà ṣe bẹ́ẹ̀ ni ìfòòró àti ìbàjẹ́ tó tóbi kò fi níí wà lórí ilẹ̀.
Verse 74
وَٱلَّذِينَ ءَامَنُوا۟ وَهَاجَرُوا۟ وَجَـٰهَدُوا۟ فِى سَبِيلِ ٱللَّهِ وَٱلَّذِينَ ءَاوَوا۟ وَّنَصَرُوٓا۟ أُو۟لَـٰٓئِكَ هُمُ ٱلْمُؤْمِنُونَ حَقًّا ۚ لَّهُم مَّغْفِرَةٌ وَرِزْقٌ كَرِيمٌ
Transliteration wa-alladhīna āmanū wahājarū wajāhadū fī sabīli l-lahi wa-alladhīna āwaw wanaṣarū ulāika humu l-mu'minūna ḥaqqan lahum maghfiratun wariz'qun karīmun
Yoruba Àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n gbé ìlú wọn jù sílẹ̀, tí wọ́n sì jagun l’ójú ọ̀nà (ẹ̀sìn) Allāhu àti àwọn tó gbà wọ́n sọ́dọ̀ (nínú ìlú), tí wọ́n sì ràn wọ́n lọ́wọ́; ní ti òdodo àwọn wọ̀nyẹn, àwọn ni onígbàgbọ́ òdodo. Àforíjìn àti arísìkí alápọ̀n-ọ́nlé sì wà fún wọn.
Verse 75
وَٱلَّذِينَ ءَامَنُوا۟ مِنۢ بَعْدُ وَهَاجَرُوا۟ وَجَـٰهَدُوا۟ مَعَكُمْ فَأُو۟لَـٰٓئِكَ مِنكُمْ ۚ وَأُو۟لُوا۟ ٱلْأَرْحَامِ بَعْضُهُمْ أَوْلَىٰ بِبَعْضٍ فِى كِتَـٰبِ ٱللَّهِ ۗ إِنَّ ٱللَّهَ بِكُلِّ شَىْءٍ عَلِيمٌۢ
Transliteration wa-alladhīna āmanū min baʿdu wahājarū wajāhadū maʿakum fa-ulāika minkum wa-ulū l-arḥāmi baʿḍuhum awlā bibaʿḍin fī kitābi l-lahi inna l-laha bikulli shayin ʿalīmun
Yoruba Àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo lẹ́yìn (wọn), tí wọ́n gbé ìlú wọn jù sílẹ̀, tí wọ́n sì jagun ẹ̀sìn pẹ̀lú yín, àwọn wọ̀nyẹn náà wà lára yín. Àti pé àwọn ìbátan, apá kan wọn ní ẹ̀tọ́ jùlọ sí apá kan (nípa ogún jíjẹ) nínú Tírà Allāhu. Dájúdájú Allāhu ni Onímọ̀ nípa gbogbo n̄ǹkan.
Read Surah Al-Anfal in another language
- English (word by word)
- Albanian
- Amazigh
- Amharic
- Assamese
- Azerbaijani
- Bambara
- Bangla
- Bosnian
- Bulgarian
- Chechen
- Chinese
- Czech
- Dari
- Dhivehi
- Dutch
- Finnish
- French
- German
- Gujarati
- Hausa
- Hebrew
- Hindi
- Indonesian
- Italian
- Japanese
- Kannada
- Kazakh
- Khmer
- Kinyarwanda
- Korean
- Kurdish
- Luganda
- Malay
- Malayalam
- Maranao
- Marathi
- Nepali
- Norwegian
- Oromo
- Pashto
- Persian
- Polish
- Portuguese
- Romanian
- Russian
- Sindhi
- Sinhala
- Somali
- Spanish
- Swahili
- Swedish
- Tagalog
- Tajik
- Tamil
- Tatar
- Telugu
- Thai
- Turkish
- Ukrainian
- Urdu
- Uyghur
- Uzbek
- Vietnamese
- Yao
All 114 surahs in Yoruba: the Qur’an in Yoruba.
Yoruba translation: Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni, from Quran.com. Transliteration: Quran.com. Recitation: Mishary Alafasy, from EveryAyah.com. MyDugsi is a learning aid, not a replacement for a qualified teacher.