MyDugsiStart learning

Surah Ghafir in Yoruba: translation and audio

Surah 40 · غافر · The Forgiver · 85 verses

Surah Ghafir verse by verse: the Arabic with a recitation you can repeat, the transliteration, and the Yoruba translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni. For the meaning of every word, see Surah Ghafir word by word in English.

Verse 1

حمٓ

Transliteration hha-meem

Yoruba Hā mīm. (Allāhu ló mọ ohun tí Ó gbàlérò pẹ̀lú àwọn háràfí náà.)1

Verse 2

تَنزِيلُ ٱلْكِتَـٰبِ مِنَ ٱللَّهِ ٱلْعَزِيزِ ٱلْعَلِيمِ

Transliteration tanzīlu l-kitābi mina l-lahi l-ʿazīzi l-ʿalīmi

Yoruba Tírà náà sọ̀kalẹ̀ díẹ̀ díẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Allāhu, Alágbára, Onímọ̀,

Verse 3

غَافِرِ ٱلذَّنۢبِ وَقَابِلِ ٱلتَّوْبِ شَدِيدِ ٱلْعِقَابِ ذِى ٱلطَّوْلِ ۖ لَآ إِلَـٰهَ إِلَّا هُوَ ۖ إِلَيْهِ ٱلْمَصِيرُ

Transliteration ghāfiri l-dhanbi waqābili l-tawbi shadīdi l-ʿiqābi dhī l-ṭawli lā ilāha illā huwa ilayhi l-maṣīru

Yoruba Aláforíjìn-ẹ̀ṣẹ̀, Olùgba-ìronúpìwàdà, Ẹni líle níbi ìyà, Ọlọ́rẹ, kò sí ọlọ́hun kan tí a gbọ́dọ̀ máa jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo àyàfi Òun. Ọ̀dọ̀ Rẹ̀ ni àbọ̀ ẹ̀dá.

Verse 4

مَا يُجَـٰدِلُ فِىٓ ءَايَـٰتِ ٱللَّهِ إِلَّا ٱلَّذِينَ كَفَرُوا۟ فَلَا يَغْرُرْكَ تَقَلُّبُهُمْ فِى ٱلْبِلَـٰدِ

Transliteration mā yujādilu fī āyāti l-lahi illā alladhīna kafarū falā yaghrur'ka taqallubuhum fī l-bilādi

Yoruba Kò sí ẹni tí ó máa ṣe àtakò sí àwọn āyah Allāhu àfi àwọn tó ṣàì gbàgbọ́. Nítorí náà, má ṣe jẹ́ kí ìgbòkègbodò wọn nínú ìlú kó ẹ̀tàn bá ọ.

Verse 5

كَذَّبَتْ قَبْلَهُمْ قَوْمُ نُوحٍ وَٱلْأَحْزَابُ مِنۢ بَعْدِهِمْ ۖ وَهَمَّتْ كُلُّ أُمَّةٍۭ بِرَسُولِهِمْ لِيَأْخُذُوهُ ۖ وَجَـٰدَلُوا۟ بِٱلْبَـٰطِلِ لِيُدْحِضُوا۟ بِهِ ٱلْحَقَّ فَأَخَذْتُهُمْ ۖ فَكَيْفَ كَانَ عِقَابِ

Transliteration kadhabat qablahum qawmu nūḥin wal-aḥzābu min baʿdihim wahammat kullu ummatin birasūlihim liyakhudhūhu wajādalū bil-bāṭili liyud'ḥiḍū bihi l-ḥaqa fa-akhadhtuhum fakayfa kāna ʿiqābi

Yoruba Ìjọ (Ànábì) Nūh pe òdodo ní irọ́ ṣíwájú wọn. Àwọn ìjọ (mìíràn) lẹ́yìn wọn (náà ṣe bẹ́ẹ̀). Ìjọ kọ̀ọ̀kan ló gbèrò láti ki Òjíṣẹ́ wọn mọ́lẹ̀. Wọ́n fi irọ́ ja òdodo níyàn nítorí kí wọ́n lè fi wó òdodo lulẹ̀. Mo sì gbá wọn mú. Nítorí náà, báwo ni ìyà (tí Mo fi jẹ wọ́n) ti rí (lára wọn ná)!

Verse 6

وَكَذَٰلِكَ حَقَّتْ كَلِمَتُ رَبِّكَ عَلَى ٱلَّذِينَ كَفَرُوٓا۟ أَنَّهُمْ أَصْحَـٰبُ ٱلنَّارِ

Transliteration wakadhālika ḥaqqat kalimatu rabbika ʿalā alladhīna kafarū annahum aṣḥābu l-nāri

Yoruba Àti pé báyẹn ni ọ̀rọ̀ Olúwa rẹ ṣe kò lórí àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ pé: “Dájúdájú àwọn ni èrò inú Iná.”

Verse 7

ٱلَّذِينَ يَحْمِلُونَ ٱلْعَرْشَ وَمَنْ حَوْلَهُۥ يُسَبِّحُونَ بِحَمْدِ رَبِّهِمْ وَيُؤْمِنُونَ بِهِۦ وَيَسْتَغْفِرُونَ لِلَّذِينَ ءَامَنُوا۟ رَبَّنَا وَسِعْتَ كُلَّ شَىْءٍ رَّحْمَةً وَعِلْمًا فَٱغْفِرْ لِلَّذِينَ تَابُوا۟ وَٱتَّبَعُوا۟ سَبِيلَكَ وَقِهِمْ عَذَابَ ٱلْجَحِيمِ

Transliteration alladhīna yaḥmilūna l-ʿarsha waman ḥawlahu yusabbiḥūna biḥamdi rabbihim wayu'minūna bihi wayastaghfirūna lilladhīna āmanū rabbanā wasiʿ'ta kulla shayin raḥmatan waʿil'man fa-igh'fir lilladhīna tābū wa-ittabaʿū sabīlaka waqihim ʿadhāba l-jaḥīmi

Yoruba Àwọn tó gbé Ìtẹ́-ọlá náà rù àti àwọn tó wà ní àyíká rẹ̀, wọ́n ń ṣe àfọ̀mọ́ pẹ̀lú ìdúpẹ́ fún Olúwa wọn. Wọ́n ní ìgbàgbọ́ òdodo nínú Allāhu. Wọ́n sì ń tọrọ àforíjìn fún àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo (báyìí pé): “Olúwa wa, ìkẹ́ àti ìmọ̀ (Rẹ) gbòòrò ju gbogbo n̄ǹkan lọ, nítorí náà, ṣàforíjìn fún àwọn tó ronú pìwàdà, tí wọ́n sì tẹ̀lé ojú-ọ̀nà Rẹ. Kí O sì ṣọ́ wọn nínú ìyà iná Jẹhīm.

Verse 8

رَبَّنَا وَأَدْخِلْهُمْ جَنَّـٰتِ عَدْنٍ ٱلَّتِى وَعَدتَّهُمْ وَمَن صَلَحَ مِنْ ءَابَآئِهِمْ وَأَزْوَٰجِهِمْ وَذُرِّيَّـٰتِهِمْ ۚ إِنَّكَ أَنتَ ٱلْعَزِيزُ ٱلْحَكِيمُ

Transliteration rabbanā wa-adkhil'hum jannāti ʿadnin allatī waʿadttahum waman ṣalaḥa min ābāihim wa-azwājihim wadhurriyyātihim innaka anta l-ʿazīzu l-ḥakīmu

Yoruba Olúwa wa, fi wọ́n sínú àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra gbére èyí tí Ó ṣe ní àdéhùn fún àwọn àti ẹni tó ṣe iṣẹ́ rere nínú àwọn bàbá wọn, àwọn aya wọn àti àwọn àrọ́mọdọ́mọ wọn. Dájúdájú Ìwọ, Ìwọ ni Alágbára, Ọlọ́gbọ́n.

Verse 9

وَقِهِمُ ٱلسَّيِّـَٔاتِ ۚ وَمَن تَقِ ٱلسَّيِّـَٔاتِ يَوْمَئِذٍ فَقَدْ رَحِمْتَهُۥ ۚ وَذَٰلِكَ هُوَ ٱلْفَوْزُ ٱلْعَظِيمُ

Transliteration waqihimu l-sayiāti waman taqi l-sayiāti yawma-idhin faqad raḥim'tahu wadhālika huwa l-fawzu l-ʿaẓīmu

Yoruba Ṣọ́ wọn nínú àwọn aburú. Ẹnikẹ́ni tí O bá ṣọ́ níbi àwọn aburú (ìyà) ní ọjọ́ yẹn, dájúdájú O ti kẹ́ ẹ. Ìyẹn sì ni èrèǹjẹ ńlá.”

Verse 10

إِنَّ ٱلَّذِينَ كَفَرُوا۟ يُنَادَوْنَ لَمَقْتُ ٱللَّهِ أَكْبَرُ مِن مَّقْتِكُمْ أَنفُسَكُمْ إِذْ تُدْعَوْنَ إِلَى ٱلْإِيمَـٰنِ فَتَكْفُرُونَ

Transliteration inna alladhīna kafarū yunādawna lamaqtu l-lahi akbaru min maqtikum anfusakum idh tud'ʿawna ilā l-īmāni fatakfurūna

Yoruba Dájúdájú àwọn tó ṣàì gbàgbọ́, wọn yóò pè wọ́n (láti sọ fún wọn nínú Iná pé): “Dájúdájú ìbínú ti Allāhu tóbi ju ìbínú tí ẹ̀ ń bí síra yín (nínú Iná, ṣebí) nígbà tí wọ́n ń pè yín síbi ìgbàgbọ́ òdodo, ńṣe ni ẹ̀ ń ṣàì gbàgbọ́.”

Verse 11

قَالُوا۟ رَبَّنَآ أَمَتَّنَا ٱثْنَتَيْنِ وَأَحْيَيْتَنَا ٱثْنَتَيْنِ فَٱعْتَرَفْنَا بِذُنُوبِنَا فَهَلْ إِلَىٰ خُرُوجٍ مِّن سَبِيلٍ

Transliteration qālū rabbanā amattanā ith'natayni wa-aḥyaytanā ith'natayni fa-iʿ'tarafnā bidhunūbinā fahal ilā khurūjin min sabīlin

Yoruba Wọ́n wí pé: “Olúwa wa, O pa wá ní ẹ̀ẹ̀ méjì. O sì ji wá ní ẹ̀ẹ̀ méjì.Nítorí náà, a jẹ́wọ́ àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa. Ǹjẹ́ ọ̀nà kan wà láti jáde (padà sí ilé ayé) bí?”

Verse 12

ذَٰلِكُم بِأَنَّهُۥٓ إِذَا دُعِىَ ٱللَّهُ وَحْدَهُۥ كَفَرْتُمْ ۖ وَإِن يُشْرَكْ بِهِۦ تُؤْمِنُوا۟ ۚ فَٱلْحُكْمُ لِلَّهِ ٱلْعَلِىِّ ٱلْكَبِيرِ

Transliteration dhālikum bi-annahu idhā duʿiya l-lahu waḥdahu kafartum wa-in yush'rak bihi tu'minū fal-ḥuk'mu lillahi l-ʿaliyi l-kabīri

Yoruba (Ẹ wà nínú Iná) yẹn nítorí pé dájúdájú nígbà tí wọ́n bá pe Allāhu nìkan ṣoṣo, ẹ̀yin ṣàì gbàgbọ́. Nígbà tí wọ́n bá ṣẹbọ sí I, ẹ sì máa gbàgbọ́ (nínú ẹbọ). Nítorí náà, ìdájọ́ ń jẹ́ ti Allāhu, Ó ga, Ó tóbi.

Verse 13

هُوَ ٱلَّذِى يُرِيكُمْ ءَايَـٰتِهِۦ وَيُنَزِّلُ لَكُم مِّنَ ٱلسَّمَآءِ رِزْقًا ۚ وَمَا يَتَذَكَّرُ إِلَّا مَن يُنِيبُ

Transliteration huwa alladhī yurīkum āyātihi wayunazzilu lakum mina l-samāi riz'qan wamā yatadhakkaru illā man yunību

Yoruba Òun ni Ẹni tó ń fi àwọn àmì Rẹ̀ hàn yín. Ó sì ń sọ arísìkí kalẹ̀ fún yín láti sánmọ̀. Kò sí ẹni tó ń lo ìrántí àfi ẹni tó ń ṣẹ́rí padà sí ọ̀dọ̀ Allāhu (nípasẹ̀ ìronúpìwàdà).

Verse 14

فَٱدْعُوا۟ ٱللَّهَ مُخْلِصِينَ لَهُ ٱلدِّينَ وَلَوْ كَرِهَ ٱلْكَـٰفِرُونَ

Transliteration fa-id'ʿū l-laha mukh'liṣīna lahu l-dīna walaw kariha l-kāfirūna

Yoruba Nítorí náà, ẹ pe Allāhu lẹ́ni tí yóò máa fi àfọ̀mọ́-ọkàn (àníyàn mímọ́) ṣe ẹ̀sìn fún Un.àwọn aláìgbàgbọ́ ìbáà kórira Rẹ̀.

Verse 15

رَفِيعُ ٱلدَّرَجَـٰتِ ذُو ٱلْعَرْشِ يُلْقِى ٱلرُّوحَ مِنْ أَمْرِهِۦ عَلَىٰ مَن يَشَآءُ مِنْ عِبَادِهِۦ لِيُنذِرَ يَوْمَ ٱلتَّلَاقِ

Transliteration rafīʿu l-darajāti dhū l-ʿarshi yul'qī l-rūḥa min amrihi ʿalā man yashāu min ʿibādihi liyundhira yawma l-talāqi

Yoruba (Allāhu) Ẹni tó ni gbogbo ipò àjùlọ, Olúwa Ìtẹ́-ọlá, Ó ń fi ìmísí mímọ́ ránṣẹ́ pẹ̀lú àṣẹ Rẹ̀ sí ẹni tí Ó bá fẹ́ nínú àwọn ẹrúsìn Rẹ̀nítorì kí ó lè fi ṣèkìlọ̀ nípa Ọjọ́ ìpàdé náà.

Verse 16

يَوْمَ هُم بَـٰرِزُونَ ۖ لَا يَخْفَىٰ عَلَى ٱللَّهِ مِنْهُمْ شَىْءٌ ۚ لِّمَنِ ٱلْمُلْكُ ٱلْيَوْمَ ۖ لِلَّهِ ٱلْوَٰحِدِ ٱلْقَهَّارِ

Transliteration yawma hum bārizūna lā yakhfā ʿalā l-lahi min'hum shayon limani l-mul'ku l-yawma lillahi l-wāḥidi l-qahāri

Yoruba Ní ọjọ́ tí wọn yóò yọ jáde (láti inú sàréè), kiní kan kò sì níí pamọ́ nípa wọn fún Allāhu. (Allāhu yó sì sọ pé): “Ti ta ni ìjọba ní ọjọ́ òní?” Ti Allāhu, Ọ̀kan ṣoṣo, Olùborí ni.

Verse 17

ٱلْيَوْمَ تُجْزَىٰ كُلُّ نَفْسٍۭ بِمَا كَسَبَتْ ۚ لَا ظُلْمَ ٱلْيَوْمَ ۚ إِنَّ ٱللَّهَ سَرِيعُ ٱلْحِسَابِ

Transliteration al-yawma tuj'zā kullu nafsin bimā kasabat lā ẓul'ma l-yawma inna l-laha sarīʿu l-ḥisābi

Yoruba Ní òní ni A óò san ẹ̀mí kọ̀ọ̀kan ní ẹ̀san ohun tí ó ṣe níṣẹ́. Kò sì sí àbòsí kan ní òní. Dájúdájú Allāhu ni Olùyára níbi ìṣírò-iṣẹ́.

Verse 18

وَأَنذِرْهُمْ يَوْمَ ٱلْـَٔازِفَةِ إِذِ ٱلْقُلُوبُ لَدَى ٱلْحَنَاجِرِ كَـٰظِمِينَ ۚ مَا لِلظَّـٰلِمِينَ مِنْ حَمِيمٍ وَلَا شَفِيعٍ يُطَاعُ

Transliteration wa-andhir'hum yawma l-āzifati idhi l-qulūbu ladā l-ḥanājiri kāẓimīna mā lilẓẓālimīna min ḥamīmin walā shafīʿin yuṭāʿu

Yoruba Àti pé ṣèkìlọ̀ fún wọn nípa ọjọ́ tí ó súnmọ́ (ìyẹn Ọjọ́ Àjíǹde). Nígbà tí àwọn ọkàn bá ga dé gògòńgò, tí ó máa kún fún ìbànújẹ́, kò níí sí ọ̀rẹ́ ìmùlẹ̀ àti olùṣìpẹ̀ kan tí wọ́n máa tẹ̀lé ọ̀rọ̀ rẹ̀ lórí (ọ̀rọ̀) àwọn alábòsí.

Verse 19

يَعْلَمُ خَآئِنَةَ ٱلْأَعْيُنِ وَمَا تُخْفِى ٱلصُّدُورُ

Transliteration yaʿlamu khāinata l-aʿyuni wamā tukh'fī l-ṣudūru

Yoruba (Allāhu) mọ ojú ìjàǹbá àti ohun tí àwọn ọkàn fi pamọ́.1

Verse 20

وَٱللَّهُ يَقْضِى بِٱلْحَقِّ ۖ وَٱلَّذِينَ يَدْعُونَ مِن دُونِهِۦ لَا يَقْضُونَ بِشَىْءٍ ۗ إِنَّ ٱللَّهَ هُوَ ٱلسَّمِيعُ ٱلْبَصِيرُ

Transliteration wal-lahu yaqḍī bil-ḥaqi wa-alladhīna yadʿūna min dūnihi lā yaqḍūna bishayin inna l-laha huwa l-samīʿu l-baṣīru

Yoruba Àti pé Allāhu l’Ó máa fi òdodo dájọ́. Àwọn tí wọ́n ń pè lẹ́yìn Rẹ̀, wọn kò lè ṣe ìdájọ́ kan kan. Dájúdájú Allāhu, Òun ni Olùgbọ́, Olùríran.

Verse 21

۞ أَوَلَمْ يَسِيرُوا۟ فِى ٱلْأَرْضِ فَيَنظُرُوا۟ كَيْفَ كَانَ عَـٰقِبَةُ ٱلَّذِينَ كَانُوا۟ مِن قَبْلِهِمْ ۚ كَانُوا۟ هُمْ أَشَدَّ مِنْهُمْ قُوَّةً وَءَاثَارًا فِى ٱلْأَرْضِ فَأَخَذَهُمُ ٱللَّهُ بِذُنُوبِهِمْ وَمَا كَانَ لَهُم مِّنَ ٱللَّهِ مِن وَاقٍ

Transliteration awalam yasīrū fī l-arḍi fayanẓurū kayfa kāna ʿāqibatu alladhīna kānū min qablihim kānū hum ashadda min'hum quwwatan waāthāran fī l-arḍi fa-akhadhahumu l-lahu bidhunūbihim wamā kāna lahum mina l-lahi min wāqin

Yoruba Ṣé wọn kò rìn kiri lórí ilẹ̀ kí wọ́n wo bí ìkángun àwọn tó ṣíwájú wọn ṣe rí? Wọ́n ní agbára jù wọ́n lọ. Wọ́n sì lo ilẹ̀ (fún oko dídá jù wọ́n lọ). Síbẹ̀síbẹ̀ Allāhu mú wọn nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Kò sì sí olùṣọ́ kan fún wọn (níbi ìyà) Allāhu.

Verse 22

ذَٰلِكَ بِأَنَّهُمْ كَانَت تَّأْتِيهِمْ رُسُلُهُم بِٱلْبَيِّنَـٰتِ فَكَفَرُوا۟ فَأَخَذَهُمُ ٱللَّهُ ۚ إِنَّهُۥ قَوِىٌّ شَدِيدُ ٱلْعِقَابِ

Transliteration dhālika bi-annahum kānat tatīhim rusuluhum bil-bayināti fakafarū fa-akhadhahumu l-lahu innahu qawiyyun shadīdu l-ʿiqābi

Yoruba Ìyẹn nítorí pé, àwọn Òjíṣẹ́ wọn ń wá bá wọn pẹ̀lú àwọn ẹ̀rí tó yanjú, ṣùgbọ́n wọ́n ṣàì gbàgbọ́. Nítorí náà, Allāhu mú wọn. Dájúdájú Òun ni Alágbára, Ẹni líle níbi ìyà.

Verse 23

وَلَقَدْ أَرْسَلْنَا مُوسَىٰ بِـَٔايَـٰتِنَا وَسُلْطَـٰنٍ مُّبِينٍ

Transliteration walaqad arsalnā mūsā biāyātinā wasul'ṭānin mubīnin

Yoruba Dájúdájú A fi àwọn àmì Wa àti ẹ̀rí tó yanjú rán (Ànábì) Mūsā níṣẹ́

Verse 24

إِلَىٰ فِرْعَوْنَ وَهَـٰمَـٰنَ وَقَـٰرُونَ فَقَالُوا۟ سَـٰحِرٌ كَذَّابٌ

Transliteration ilā fir'ʿawna wahāmāna waqārūna faqālū sāḥirun kadhābun

Yoruba sí Fir‘aon àti Hāmọ̄n àti Ƙọ̄rūn. Ṣùgbọ́n wọ́n wí pé: “Òpìdán, òpùrọ́ ni (Ànábì Mūsā).”

Verse 25

فَلَمَّا جَآءَهُم بِٱلْحَقِّ مِنْ عِندِنَا قَالُوا۟ ٱقْتُلُوٓا۟ أَبْنَآءَ ٱلَّذِينَ ءَامَنُوا۟ مَعَهُۥ وَٱسْتَحْيُوا۟ نِسَآءَهُمْ ۚ وَمَا كَيْدُ ٱلْكَـٰفِرِينَ إِلَّا فِى ضَلَـٰلٍ

Transliteration falammā jāahum bil-ḥaqi min ʿindinā qālū uq'tulū abnāa alladhīna āmanū maʿahu wa-is'taḥyū nisāahum wamā kaydu l-kāfirīna illā fī ḍalālin

Yoruba Nígbà tí ó mú òdodo náà dé ọ̀dọ̀ wọn láti ọ̀dọ̀ Wa, wọ́n wí pé: “Ẹ pa àwọn ọmọkùnrin àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo nínú Allāhu pẹ̀lú rẹ̀, kí ẹ sì fi àwọn ọmọbìnrin wọn sílẹ̀.” Ète àwọn aláìgbàgbọ́ kò sí nínú kiní kan bí kò ṣe nínú ìṣìnà.

Verse 26

وَقَالَ فِرْعَوْنُ ذَرُونِىٓ أَقْتُلْ مُوسَىٰ وَلْيَدْعُ رَبَّهُۥٓ ۖ إِنِّىٓ أَخَافُ أَن يُبَدِّلَ دِينَكُمْ أَوْ أَن يُظْهِرَ فِى ٱلْأَرْضِ ٱلْفَسَادَ

Transliteration waqāla fir'ʿawnu dharūnī aqtul mūsā walyadʿu rabbahu innī akhāfu an yubaddila dīnakum aw an yuẓ'hira fī l-arḍi l-fasāda

Yoruba Fir‘aon wí pé: “Ẹ fi mí sílẹ̀ kí n̄g pa Mūsā, kí ó sì pe Olúwa rẹ̀ (wò bóyá Ó máa gbà á sílẹ̀). Dájúdájú èmi ń bẹ̀rù pé ó máa yí ẹ̀sìn yín padà tàbí pé ó máa ṣàfi hàn ìbàjẹ́ lórí ilẹ̀.”

Verse 27

وَقَالَ مُوسَىٰٓ إِنِّى عُذْتُ بِرَبِّى وَرَبِّكُم مِّن كُلِّ مُتَكَبِّرٍ لَّا يُؤْمِنُ بِيَوْمِ ٱلْحِسَابِ

Transliteration waqāla mūsā innī ʿudh'tu birabbī warabbikum min kulli mutakabbirin lā yu'minu biyawmi l-ḥisābi

Yoruba (Ànábì) Mūsā sọ pé: “Dájúdájú èmi sá di Olúwa mi àti Olúwa yín kúrò lọ́wọ́ gbogbo onígbèéraga, tí kò ní ìgbàgbọ́ òdodo nínú Ọjọ́ ìṣírò-iṣẹ́.

Verse 28

وَقَالَ رَجُلٌ مُّؤْمِنٌ مِّنْ ءَالِ فِرْعَوْنَ يَكْتُمُ إِيمَـٰنَهُۥٓ أَتَقْتُلُونَ رَجُلًا أَن يَقُولَ رَبِّىَ ٱللَّهُ وَقَدْ جَآءَكُم بِٱلْبَيِّنَـٰتِ مِن رَّبِّكُمْ ۖ وَإِن يَكُ كَـٰذِبًا فَعَلَيْهِ كَذِبُهُۥ ۖ وَإِن يَكُ صَادِقًا يُصِبْكُم بَعْضُ ٱلَّذِى يَعِدُكُمْ ۖ إِنَّ ٱللَّهَ لَا يَهْدِى مَنْ هُوَ مُسْرِفٌ كَذَّابٌ

Transliteration waqāla rajulun mu'minun min āli fir'ʿawna yaktumu īmānahu ataqtulūna rajulan an yaqūla rabbiya l-lahu waqad jāakum bil-bayināti min rabbikum wa-in yaku kādhiban faʿalayhi kadhibuhu wa-in yaku ṣādiqan yuṣib'kum baʿḍu alladhī yaʿidukum inna l-laha lā yahdī man huwa mus'rifun kadhābun

Yoruba Ọkùnrin onígbàgbọ́ òdodo kan tó ń fi ìgbàgbọ́ rẹ̀ pamọ́ nínú àwọn ènìyàn Fir‘aon sọ pé: “Ṣé ẹ máa pa ọkùnrin kan nítorí pé ó ń sọ pé, “Allāhu ni Olúwa mi.” Ó sì kúkú ti mú àwọn ẹ̀rí tó yanjú wá ba yín láti ọ̀dọ̀ Olúwa yín. Tí ó bá jẹ́ òpùrọ́, (ìyà) irọ́ rẹ̀ wà lórí rẹ̀. Tí ó bá sì jẹ́ olódodo, apá kan èyí tí ó ṣe ní ìlérí fún yín yó sì kò le yín lórí. Dájúdájú Allāhu kò níí fi ọ̀nà mọ ẹni tí ó jẹ́ aláṣejù, òpùrọ́.

Verse 29

يَـٰقَوْمِ لَكُمُ ٱلْمُلْكُ ٱلْيَوْمَ ظَـٰهِرِينَ فِى ٱلْأَرْضِ فَمَن يَنصُرُنَا مِنۢ بَأْسِ ٱللَّهِ إِن جَآءَنَا ۚ قَالَ فِرْعَوْنُ مَآ أُرِيكُمْ إِلَّا مَآ أَرَىٰ وَمَآ أَهْدِيكُمْ إِلَّا سَبِيلَ ٱلرَّشَادِ

Transliteration yāqawmi lakumu l-mul'ku l-yawma ẓāhirīna fī l-arḍi faman yanṣurunā min basi l-lahi in jāanā qāla fir'ʿawnu mā urīkum illā mā arā wamā ahdīkum illā sabīla l-rashādi

Yoruba Ẹ̀yin ènìyàn mi, ẹ̀yin l’ẹ ni ìjọba lónìí, tí ẹ ga jùlọ lórí ilẹ̀ náà (ìyẹn ilẹ̀ Misrọ). Ṣùgbọ́n ta ni ó máa ràn wá lọ́wọ́ tí ìyà Allāhu bá dé bá wa?” Fir‘aon wí pé: “Èmi kò fi n̄ǹkan kan hàn yín bí kò ṣe ohun tí mo rí (nínú òye mi). Èmi kò sì tọ yín sí ọ̀nà kan bí kò ṣe ojú ọ̀nà ìmọ̀nà.”

Verse 30

وَقَالَ ٱلَّذِىٓ ءَامَنَ يَـٰقَوْمِ إِنِّىٓ أَخَافُ عَلَيْكُم مِّثْلَ يَوْمِ ٱلْأَحْزَابِ

Transliteration waqāla alladhī āmana yāqawmi innī akhāfu ʿalaykum mith'la yawmi l-aḥzābi

Yoruba Ẹni tó gbàgbọ́ ní òdodo tún sọ pé: “Ẹ̀yin ènìyàn mi, dájúdájú irú ọjọ́ (ẹ̀san ìyà tó ṣẹlẹ̀ sí) àwọn ọmọ-ogun oníjọ ni èmi ń páyà lórí yín;

Verse 31

مِثْلَ دَأْبِ قَوْمِ نُوحٍ وَعَادٍ وَثَمُودَ وَٱلَّذِينَ مِنۢ بَعْدِهِمْ ۚ وَمَا ٱللَّهُ يُرِيدُ ظُلْمًا لِّلْعِبَادِ

Transliteration mith'la dabi qawmi nūḥin waʿādin wathamūda wa-alladhīna min baʿdihim wamā l-lahu yurīdu ẓul'man lil'ʿibādi

Yoruba Irú ìṣe (ìparun tó ṣẹlẹ̀ sí àwọn) ènìyàn Nūh, ‘Ād, Thamūd àti àwọn tó tẹ̀lé wọn. Allāhu kò sì gbèrò àbòsí sí àwọn ẹrúsìn náà.

Verse 32

وَيَـٰقَوْمِ إِنِّىٓ أَخَافُ عَلَيْكُمْ يَوْمَ ٱلتَّنَادِ

Transliteration wayāqawmi innī akhāfu ʿalaykum yawma l-tanādi

Yoruba Ẹ̀yin ènìyàn mi, dájúdájú èmi ń páyà Ọjọ́ ìpè fún yín.1

Verse 33

يَوْمَ تُوَلُّونَ مُدْبِرِينَ مَا لَكُم مِّنَ ٱللَّهِ مِنْ عَاصِمٍ ۗ وَمَن يُضْلِلِ ٱللَّهُ فَمَا لَهُۥ مِنْ هَادٍ

Transliteration yawma tuwallūna mud'birīna mā lakum mina l-lahi min ʿāṣimin waman yuḍ'lili l-lahu famā lahu min hādin

Yoruba Ọjọ́ tí ẹ máa pẹ̀yìndà láti sá lọ; kò sì níí sí aláàbò kan fún yín lọ́dọ̀ Allāhu. Àti pé ẹni tí Allāhu bá ṣì lọ́nà, kò lè sí afinimọ̀nà kan fún un.

Verse 34

وَلَقَدْ جَآءَكُمْ يُوسُفُ مِن قَبْلُ بِٱلْبَيِّنَـٰتِ فَمَا زِلْتُمْ فِى شَكٍّ مِّمَّا جَآءَكُم بِهِۦ ۖ حَتَّىٰٓ إِذَا هَلَكَ قُلْتُمْ لَن يَبْعَثَ ٱللَّهُ مِنۢ بَعْدِهِۦ رَسُولًا ۚ كَذَٰلِكَ يُضِلُّ ٱللَّهُ مَنْ هُوَ مُسْرِفٌ مُّرْتَابٌ

Transliteration walaqad jāakum yūsufu min qablu bil-bayināti famā zil'tum fī shakkin mimmā jāakum bihi ḥattā idhā halaka qul'tum lan yabʿatha l-lahu min baʿdihi rasūlan kadhālika yuḍillu l-lahu man huwa mus'rifun mur'tābun

Yoruba Àti pé dájúdájú (Ànábì) Yūsuf ti tọ̀ yín wá ṣíwájú pẹ̀lú àwọn àlàyé ọ̀rọ̀ tó yanjú, ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò yé wà nínú iyèméjì nípa ohun tí ó mú wá ba yín títí di ìgbà tí ó fi kú, tí ẹ fi wí pé: “Allāhu kò níí gbé Òjíṣẹ́ kan dìde mọ́ lẹ́yìn rẹ̀. Báyẹn ni Allāhu ṣe ń sọ ẹni tí ó jẹ́ aláṣejù, oníyèméjì nù.”

Verse 35

ٱلَّذِينَ يُجَـٰدِلُونَ فِىٓ ءَايَـٰتِ ٱللَّهِ بِغَيْرِ سُلْطَـٰنٍ أَتَىٰهُمْ ۖ كَبُرَ مَقْتًا عِندَ ٱللَّهِ وَعِندَ ٱلَّذِينَ ءَامَنُوا۟ ۚ كَذَٰلِكَ يَطْبَعُ ٱللَّهُ عَلَىٰ كُلِّ قَلْبِ مُتَكَبِّرٍ جَبَّارٍ

Transliteration alladhīna yujādilūna fī āyāti l-lahi bighayri sul'ṭānin atāhum kabura maqtan ʿinda l-lahi waʿinda alladhīna āmanū kadhālika yaṭbaʿu l-lahu ʿalā kulli qalbi mutakabbirin jabbārin

Yoruba Àwọn tó ń jiyàn nípa àwọn āyah Allāhu láìsí ẹ̀rí kan tí ó dé bá wọn. Ẹ̀ṣẹ̀ ńlá sì ni ní ọ̀dọ̀ Allāhu àti ní ọ̀dọ̀ àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo. Báyẹn ni Allāhu ṣe ń fi èdídí bo gbogbo ọkàn onígbèéraga, ajẹninípá.”

Verse 36

وَقَالَ فِرْعَوْنُ يَـٰهَـٰمَـٰنُ ٱبْنِ لِى صَرْحًا لَّعَلِّىٓ أَبْلُغُ ٱلْأَسْبَـٰبَ

Transliteration waqāla fir'ʿawnu yāhāmānu ib'ni lī ṣarḥan laʿallī ablughu l-asbāba

Yoruba Fir‘aon wí pé: “Hāmọ̄n, mọ ilé gíga fíofío kan fún mi nítorí kí èmi lè dé àwọn ojú ọ̀nà náà.

Verse 37

أَسْبَـٰبَ ٱلسَّمَـٰوَٰتِ فَأَطَّلِعَ إِلَىٰٓ إِلَـٰهِ مُوسَىٰ وَإِنِّى لَأَظُنُّهُۥ كَـٰذِبًا ۚ وَكَذَٰلِكَ زُيِّنَ لِفِرْعَوْنَ سُوٓءُ عَمَلِهِۦ وَصُدَّ عَنِ ٱلسَّبِيلِ ۚ وَمَا كَيْدُ فِرْعَوْنَ إِلَّا فِى تَبَابٍ

Transliteration asbāba l-samāwāti fa-aṭṭaliʿa ilā ilāhi mūsā wa-innī la-aẓunnuhu kādhiban wakadhālika zuyyina lifir'ʿawna sūu ʿamalihi waṣudda ʿani l-sabīli wamā kaydu fir'ʿawna illā fī tabābin

Yoruba Àwọn ojú ọ̀nà (inú) sánmọ̀ ni, nítorí kí èmi lè yọjú wo Ọlọ́hun Mūsā nítorí pé, dájúdájú èmi ń rò ó sí òpùrọ́.” Báyẹn ni wọ́n ṣe iṣẹ́ aburú (ọwọ́) Fir‘aon ní ọ̀ṣọ́ fún un. Wọ́n sì ṣẹ́rí rẹ̀ kúrò lójú ọ̀nà (ẹ̀sìn Allāhu). Ète Fir‘aon kò sì wà nínú kiní kan bí kò ṣe nínú òfò.

Verse 38

وَقَالَ ٱلَّذِىٓ ءَامَنَ يَـٰقَوْمِ ٱتَّبِعُونِ أَهْدِكُمْ سَبِيلَ ٱلرَّشَادِ

Transliteration waqāla alladhī āmana yāqawmi ittabiʿūni ahdikum sabīla l-rashādi

Yoruba Ẹni tó gbàgbọ́ ní òdodo tún sọ pé: “Ẹ̀yin ènìyàn mi, ẹ tẹ̀lé mi, mo máa júwe yín sí ojú ọ̀nà ìmọ̀nà.

Verse 39

يَـٰقَوْمِ إِنَّمَا هَـٰذِهِ ٱلْحَيَوٰةُ ٱلدُّنْيَا مَتَـٰعٌ وَإِنَّ ٱلْـَٔاخِرَةَ هِىَ دَارُ ٱلْقَرَارِ

Transliteration yāqawmi innamā hādhihi l-ḥayatu l-dun'yā matāʿun wa-inna l-ākhirata hiya dāru l-qarāri

Yoruba Ẹ̀yin ènìyàn mi, ìgbádùn lásán ni ìṣẹ̀mí ilé ayé yìí. Dájúdájú ọ̀run sì ni ilé gbére.

Verse 40

مَنْ عَمِلَ سَيِّئَةً فَلَا يُجْزَىٰٓ إِلَّا مِثْلَهَا ۖ وَمَنْ عَمِلَ صَـٰلِحًا مِّن ذَكَرٍ أَوْ أُنثَىٰ وَهُوَ مُؤْمِنٌ فَأُو۟لَـٰٓئِكَ يَدْخُلُونَ ٱلْجَنَّةَ يُرْزَقُونَ فِيهَا بِغَيْرِ حِسَابٍ

Transliteration man ʿamila sayyi-atan falā yuj'zā illā mith'lahā waman ʿamila ṣāliḥan min dhakarin aw unthā wahuwa mu'minun fa-ulāika yadkhulūna l-janata yur'zaqūna fīhā bighayri ḥisābin

Yoruba Ẹni tí ó bá ṣe aburú kan, Wọn kò níí san án ní ẹ̀san kan àyàfi irú rẹ̀. Ẹni tí ó bá sì ṣe iṣẹ́ rere ní ọkùnrin tàbí ní obìnrin, tí ó sì jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo,àwọn wọ̀nyẹn ni wọ́n máa wọ inú Ọgbà Ìdẹ̀ra. Wọn yóò máa pèsè ìjẹ-ìmu àti ìgbádùn fún wọn nínú rẹ̀ láì níí ní ìṣírò.2

Verse 41

۞ وَيَـٰقَوْمِ مَا لِىٓ أَدْعُوكُمْ إِلَى ٱلنَّجَوٰةِ وَتَدْعُونَنِىٓ إِلَى ٱلنَّارِ

Transliteration wayāqawmi mā lī adʿūkum ilā l-najati watadʿūnanī ilā l-nāri

Yoruba Ẹ̀yin ènìyàn mi, kí ló mú yín tí mò ń pè yín síbi ìgbàlà, tí ẹ̀yin sì ń pè mí síbi Iná?

Verse 42

تَدْعُونَنِى لِأَكْفُرَ بِٱللَّهِ وَأُشْرِكَ بِهِۦ مَا لَيْسَ لِى بِهِۦ عِلْمٌ وَأَنَا۠ أَدْعُوكُمْ إِلَى ٱلْعَزِيزِ ٱلْغَفَّـٰرِ

Transliteration tadʿūnanī li-akfura bil-lahi wa-ush'rika bihi mā laysa lī bihi ʿil'mun wa-anā adʿūkum ilā l-ʿazīzi l-ghafāri

Yoruba Ẹ̀yin ń pè mí pé kí n̄g ṣàì gbàgbọ́ nínú Allāhu, kí n̄g sì sọ n̄ǹkan tí èmi kò nímọ̀ nípa rẹ̀ di akẹgbẹ́ fún Un.Èmi sì ń pè yín sí ọ̀dọ̀ Alágbára, Aláforíjìn.

Verse 43

لَا جَرَمَ أَنَّمَا تَدْعُونَنِىٓ إِلَيْهِ لَيْسَ لَهُۥ دَعْوَةٌ فِى ٱلدُّنْيَا وَلَا فِى ٱلْـَٔاخِرَةِ وَأَنَّ مَرَدَّنَآ إِلَى ٱللَّهِ وَأَنَّ ٱلْمُسْرِفِينَ هُمْ أَصْحَـٰبُ ٱلنَّارِ

Transliteration lā jarama annamā tadʿūnanī ilayhi laysa lahu daʿwatun fī l-dun'yā walā fī l-ākhirati wa-anna maraddanā ilā l-lahi wa-anna l-mus'rifīna hum aṣḥābu l-nāri

Yoruba Kò sí tàbí-ṣùgbọ́n, dájúdájú n̄ǹkan tí ẹ̀ ń pè mí sí, kò ní ẹ̀tọ́ sí ìpè kan ní ayé àti ní ọ̀run. Àti pé dájúdájú ọ̀dọ̀ Allāhu ni àbọ̀ wa. Dájúdájú àwọn olùtayọ-ẹnu-ààlà, àwọn ni èrò inú Iná.

Verse 44

فَسَتَذْكُرُونَ مَآ أَقُولُ لَكُمْ ۚ وَأُفَوِّضُ أَمْرِىٓ إِلَى ٱللَّهِ ۚ إِنَّ ٱللَّهَ بَصِيرٌۢ بِٱلْعِبَادِ

Transliteration fasatadhkurūna mā aqūlu lakum wa-ufawwiḍu amrī ilā l-lahi inna l-laha baṣīrun bil-ʿibādi

Yoruba Nítorí náà, ẹ máa rántí ohun tí mò ń sọ fún yín. Mo sì ń fi ọ̀rọ̀ mi tì sí ọ̀dọ̀ Allāhu. Dájúdájú Allāhu ni Olùríran nípa àwọn ẹrúsìn.”

Verse 45

فَوَقَىٰهُ ٱللَّهُ سَيِّـَٔاتِ مَا مَكَرُوا۟ ۖ وَحَاقَ بِـَٔالِ فِرْعَوْنَ سُوٓءُ ٱلْعَذَابِ

Transliteration fawaqāhu l-lahu sayyiāti mā makarū waḥāqa biāli fir'ʿawna sūu l-ʿadhābi

Yoruba Allāhu sì ṣọ́ ọ níbi àwọn aburú tí wọ́n dète rẹ̀. Ìyà burúkú sì yí àwọn ènìyàn Fir‘aon po.

Verse 46

ٱلنَّارُ يُعْرَضُونَ عَلَيْهَا غُدُوًّا وَعَشِيًّا ۖ وَيَوْمَ تَقُومُ ٱلسَّاعَةُ أَدْخِلُوٓا۟ ءَالَ فِرْعَوْنَ أَشَدَّ ٱلْعَذَابِ

Transliteration al-nāru yuʿ'raḍūna ʿalayhā ghuduwwan waʿashiyyan wayawma taqūmu l-sāʿatu adkhilū āla fir'ʿawna ashadda l-ʿadhābi

Yoruba Iná ni Wọ́n yóò máà ṣẹ́rí wọn sí ní òwúrọ̀ àti ní ìrọ̀lẹ́. Àti pé ní ọjọ́ tí Àkókò náà bá dé (A máa sọ pé): “Ẹ mú àwọn ènìyàn Fir‘aon wọ inú ìyà Iná tó le jùlọ.”

Verse 47

وَإِذْ يَتَحَآجُّونَ فِى ٱلنَّارِ فَيَقُولُ ٱلضُّعَفَـٰٓؤُا۟ لِلَّذِينَ ٱسْتَكْبَرُوٓا۟ إِنَّا كُنَّا لَكُمْ تَبَعًا فَهَلْ أَنتُم مُّغْنُونَ عَنَّا نَصِيبًا مِّنَ ٱلنَّارِ

Transliteration wa-idh yataḥājjūna fī l-nāri fayaqūlu l-ḍuʿafāu lilladhīna is'takbarū innā kunnā lakum tabaʿan fahal antum mugh'nūna ʿannā naṣīban mina l-nāri

Yoruba (Rántí) nígbà tí wọ́n bá ń bá ara wọn ṣe àríyànjiyàn nínú Iná. Àwọn ọ̀lẹ yóò wí fún àwọn tí wọ́n ṣègbéraga pé: “Dájúdájú àwa jẹ́ ọmọlẹ́yìn fún yín, ǹjẹ́ ẹ̀yin lè gbé ìpín kan kúrò fún wa nínú ìyà Iná?”

Verse 48

قَالَ ٱلَّذِينَ ٱسْتَكْبَرُوٓا۟ إِنَّا كُلٌّ فِيهَآ إِنَّ ٱللَّهَ قَدْ حَكَمَ بَيْنَ ٱلْعِبَادِ

Transliteration qāla alladhīna is'takbarū innā kullun fīhā inna l-laha qad ḥakama bayna l-ʿibādi

Yoruba Àwọn tó ṣègbéraga máa wí pé: “Dájúdájú gbogbo wa l’a wà nínú rẹ̀. Dájúdájú Allāhu kúkú ti dájọ́ láààrin àwọn ẹrú náà.”

Verse 49

وَقَالَ ٱلَّذِينَ فِى ٱلنَّارِ لِخَزَنَةِ جَهَنَّمَ ٱدْعُوا۟ رَبَّكُمْ يُخَفِّفْ عَنَّا يَوْمًا مِّنَ ٱلْعَذَابِ

Transliteration waqāla alladhīna fī l-nāri likhazanati jahannama id'ʿū rabbakum yukhaffif ʿannā yawman mina l-ʿadhābi

Yoruba Àwọn tó wà nínú Iná tún máa wí fún àwọn ẹ̀ṣọ́-Iná pé: “Ẹ bá wa pe Olúwa yín, kí Ó ṣe ìyà ní fífúyẹ́ fún wa fún ọjọ́ kan.”

Verse 50

قَالُوٓا۟ أَوَلَمْ تَكُ تَأْتِيكُمْ رُسُلُكُم بِٱلْبَيِّنَـٰتِ ۖ قَالُوا۟ بَلَىٰ ۚ قَالُوا۟ فَٱدْعُوا۟ ۗ وَمَا دُعَـٰٓؤُا۟ ٱلْكَـٰفِرِينَ إِلَّا فِى ضَلَـٰلٍ

Transliteration qālū awalam taku tatīkum rusulukum bil-bayināti qālū balā qālū fa-id'ʿū wamā duʿāu l-kāfirīna illā fī ḍalālin

Yoruba Wọ́n yóò sọ pé: “Ǹjẹ́ àwọn Òjísẹ́ yín kì í mú àwọn ẹ̀rí tó yanjú wá ba yín bí?” Wọ́n á wí pé: “Bẹ́ẹ̀ ni, (wọ́n mú un wá).” Wọ́n máa sọ pé: “Ẹ ṣàdúà wò.” Àdúà (àti ìpè) àwọn aláìgbàgbọ́ kò sì jẹ́ kiní kan bí kò ṣe sínú ìṣìnà.1

Verse 51

إِنَّا لَنَنصُرُ رُسُلَنَا وَٱلَّذِينَ ءَامَنُوا۟ فِى ٱلْحَيَوٰةِ ٱلدُّنْيَا وَيَوْمَ يَقُومُ ٱلْأَشْهَـٰدُ

Transliteration innā lananṣuru rusulanā wa-alladhīna āmanū fī l-ḥayati l-dun'yā wayawma yaqūmu l-ashhādu

Yoruba Dájúdájú Àwa kúkú máa ṣàrànṣe fún àwọn Òjíṣẹ́ Wa àti àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo nínú ìgbésí ayé yìí àti ní ọjọ́ tí àwọn ẹlẹ́rìí yó dìde (ní Ọjọ́ Àjíǹde).

Verse 52

يَوْمَ لَا يَنفَعُ ٱلظَّـٰلِمِينَ مَعْذِرَتُهُمْ ۖ وَلَهُمُ ٱللَّعْنَةُ وَلَهُمْ سُوٓءُ ٱلدَّارِ

Transliteration yawma lā yanfaʿu l-ẓālimīna maʿdhiratuhum walahumu l-laʿnatu walahum sūu l-dāri

Yoruba Ní ọjọ́ tí àwáwí àwọn alábòsí kò níí ṣe wọ́n ní àǹfààní; ègún ń bẹ fún wọn, ilé (ìyà) burúkú sì wà fún wọn.

Verse 53

وَلَقَدْ ءَاتَيْنَا مُوسَى ٱلْهُدَىٰ وَأَوْرَثْنَا بَنِىٓ إِسْرَٰٓءِيلَ ٱلْكِتَـٰبَ

Transliteration walaqad ātaynā mūsā l-hudā wa-awrathnā banī is'rāīla l-kitāba

Yoruba Dájúdájú A fún (Ànábì) Mūsā ní ìmọ̀nà. A sì jogún Tírà fún àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl.

Verse 54

هُدًى وَذِكْرَىٰ لِأُو۟لِى ٱلْأَلْبَـٰبِ

Transliteration hudan wadhik'rā li-ulī l-albābi

Yoruba (Ó jẹ́) ìmọ̀nà àti ìrántí fún àwọn onílàákàyè.

Verse 55

فَٱصْبِرْ إِنَّ وَعْدَ ٱللَّهِ حَقٌّ وَٱسْتَغْفِرْ لِذَنۢبِكَ وَسَبِّحْ بِحَمْدِ رَبِّكَ بِٱلْعَشِىِّ وَٱلْإِبْكَـٰرِ

Transliteration fa-iṣ'bir inna waʿda l-lahi ḥaqqun wa-is'taghfir lidhanbika wasabbiḥ biḥamdi rabbika bil-ʿashiyi wal-ib'kāri

Yoruba Nítorí náà, ṣe sùúrù. Dájúdájú àdéhùn Allāhu ni òdodo. Tọrọ àforíjìn fún ẹ̀ṣẹ̀ rẹ.Kí o sì ṣe àfọ̀mọ́ pẹ̀lú ẹyìn fún Olúwa rẹ2 ní ìrọ̀lẹ́ àti ní òwúrọ̀ kùtùkùtù.

Verse 56

إِنَّ ٱلَّذِينَ يُجَـٰدِلُونَ فِىٓ ءَايَـٰتِ ٱللَّهِ بِغَيْرِ سُلْطَـٰنٍ أَتَىٰهُمْ ۙ إِن فِى صُدُورِهِمْ إِلَّا كِبْرٌ مَّا هُم بِبَـٰلِغِيهِ ۚ فَٱسْتَعِذْ بِٱللَّهِ ۖ إِنَّهُۥ هُوَ ٱلسَّمِيعُ ٱلْبَصِيرُ

Transliteration inna alladhīna yujādilūna fī āyāti l-lahi bighayri sul'ṭānin atāhum in fī ṣudūrihim illā kib'run mā hum bibālighīhi fa-is'taʿidh bil-lahi innahu huwa l-samīʿu l-baṣīru

Yoruba Dájúdájú àwọn tó ń jiyàn nípa àwọn āyah Allāhu láìní ẹrí kan (lọ́wọ́) tí ó wá bá wọn (láti ọ̀dọ̀ Allāhu), kò sí kiní kan nínú igbá-àyà wọn àyàfi ọkàn-gíga. Wọn kò sì lè dé ibi gíga (pẹ̀lú ọkàn gíga). Nítorí náà, sá di Allāhu. Dájúdájú Allāhu, Òun ni Olùgbọ́, Olùríran.

Verse 57

لَخَلْقُ ٱلسَّمَـٰوَٰتِ وَٱلْأَرْضِ أَكْبَرُ مِنْ خَلْقِ ٱلنَّاسِ وَلَـٰكِنَّ أَكْثَرَ ٱلنَّاسِ لَا يَعْلَمُونَ

Transliteration lakhalqu l-samāwāti wal-arḍi akbaru min khalqi l-nāsi walākinna akthara l-nāsi lā yaʿlamūna

Yoruba Dájúdájú ìṣẹ̀dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ tóbi ju ìṣẹ̀dá àwọn ènìyàn; ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ àwọn ènìyàn ni kò mọ̀.

Verse 58

وَمَا يَسْتَوِى ٱلْأَعْمَىٰ وَٱلْبَصِيرُ وَٱلَّذِينَ ءَامَنُوا۟ وَعَمِلُوا۟ ٱلصَّـٰلِحَـٰتِ وَلَا ٱلْمُسِىٓءُ ۚ قَلِيلًا مَّا تَتَذَكَّرُونَ

Transliteration wamā yastawī l-aʿmā wal-baṣīru wa-alladhīna āmanū waʿamilū l-ṣāliḥāti walā l-musīu qalīlan mā tatadhakkarūna

Yoruba Afọ́jú àti olùríran kò dọ́gba. Àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe àwọn iṣẹ́ rere àti oníṣẹ́-aburú (kò dọ́gba). Díẹ̀ l’ẹ̀ ń lò nínú ìrántí.

Verse 59

إِنَّ ٱلسَّاعَةَ لَـَٔاتِيَةٌ لَّا رَيْبَ فِيهَا وَلَـٰكِنَّ أَكْثَرَ ٱلنَّاسِ لَا يُؤْمِنُونَ

Transliteration inna l-sāʿata laātiyatun lā rayba fīhā walākinna akthara l-nāsi lā yu'minūna

Yoruba Dájúdájú Àkókò náà ń bọ̀, kò sì sí iyèméjì nínú rẹ̀. Ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ àwọn ènìyàn ni kò gbàgbọ́.

Verse 60

وَقَالَ رَبُّكُمُ ٱدْعُونِىٓ أَسْتَجِبْ لَكُمْ ۚ إِنَّ ٱلَّذِينَ يَسْتَكْبِرُونَ عَنْ عِبَادَتِى سَيَدْخُلُونَ جَهَنَّمَ دَاخِرِينَ

Transliteration waqāla rabbukumu id'ʿūnī astajib lakum inna alladhīna yastakbirūna ʿan ʿibādatī sayadkhulūna jahannama dākhirīna

Yoruba Olúwa yín sọ pé: “Ẹ pè Mí, kí N̄g jẹ́pè yín. Dájúdájú àwọn tó ń ṣègbéraga nípa jíjọ́sìn fún Mi,wọn yóò wọ inú iná Jahanamọ ní ẹni yẹpẹrẹ.”

Verse 61

ٱللَّهُ ٱلَّذِى جَعَلَ لَكُمُ ٱلَّيْلَ لِتَسْكُنُوا۟ فِيهِ وَٱلنَّهَارَ مُبْصِرًا ۚ إِنَّ ٱللَّهَ لَذُو فَضْلٍ عَلَى ٱلنَّاسِ وَلَـٰكِنَّ أَكْثَرَ ٱلنَّاسِ لَا يَشْكُرُونَ

Transliteration al-lahu alladhī jaʿala lakumu al-layla litaskunū fīhi wal-nahāra mub'ṣiran inna l-laha ladhū faḍlin ʿalā l-nāsi walākinna akthara l-nāsi lā yashkurūna

Yoruba Allāhu ni Ẹni tí Ó ṣe òru fún yín nítorí kí ẹ lè sinmi nínú rẹ̀. (Ó sì ṣe) ọ̀sán (nítorí kí ẹ lè fi) ríran. Dájúdájú Allāhu ni Ọlọ́lá-jùlọ lórí àwọn ènìyàn, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ àwọn ènìyàn kì í dúpẹ́ (fún Un).

Verse 62

ذَٰلِكُمُ ٱللَّهُ رَبُّكُمْ خَـٰلِقُ كُلِّ شَىْءٍ لَّآ إِلَـٰهَ إِلَّا هُوَ ۖ فَأَنَّىٰ تُؤْفَكُونَ

Transliteration dhālikumu l-lahu rabbukum khāliqu kulli shayin lā ilāha illā huwa fa-annā tu'fakūna

Yoruba Ìyẹn ni Allāhu, Olúwa yín, Ẹlẹ́dàá gbogbo n̄ǹkan. Kò sí ọlọ́hun kan tí ẹ gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo àyàfi Òun. Nítorí náà, báwo ni wọ́n ṣe ń ṣẹ yín lórí kúrò níbi òdodo?

Verse 63

كَذَٰلِكَ يُؤْفَكُ ٱلَّذِينَ كَانُوا۟ بِـَٔايَـٰتِ ٱللَّهِ يَجْحَدُونَ

Transliteration kadhālika yu'faku alladhīna kānū biāyāti l-lahi yajḥadūna

Yoruba Báyẹn náà ni wọ́n ṣe ń ṣẹ́ àwọn tó ń tako àwọn āyah Allāhu lórí kúrò níbi òdodo (ṣíwájú tiwọn).

Verse 64

ٱللَّهُ ٱلَّذِى جَعَلَ لَكُمُ ٱلْأَرْضَ قَرَارًا وَٱلسَّمَآءَ بِنَآءً وَصَوَّرَكُمْ فَأَحْسَنَ صُوَرَكُمْ وَرَزَقَكُم مِّنَ ٱلطَّيِّبَـٰتِ ۚ ذَٰلِكُمُ ٱللَّهُ رَبُّكُمْ ۖ فَتَبَارَكَ ٱللَّهُ رَبُّ ٱلْعَـٰلَمِينَ

Transliteration al-lahu alladhī jaʿala lakumu l-arḍa qarāran wal-samāa bināan waṣawwarakum fa-aḥsana ṣuwarakum warazaqakum mina l-ṭayibāti dhālikumu l-lahu rabbukum fatabāraka l-lahu rabbu l-ʿālamīna

Yoruba Allāhu ni Ẹni tí Ó ṣe ilẹ̀ fún yín ní ibùgbé. Ó sì ṣe sánmọ̀ ní àjà (le yín lórí). Ó ya àwòrán yín. Ó sì ya àwòrán yín dáradára. Ó pèsè arísìkí fún yín nínú àwọn n̄ǹkan dáadáa. Ìyẹn ni Allāhu, Olúwa yín. Nítorí náà, mímọ́ ni fún Allāhu, Olúwa gbogbo ẹ̀dá.

Verse 65

هُوَ ٱلْحَىُّ لَآ إِلَـٰهَ إِلَّا هُوَ فَٱدْعُوهُ مُخْلِصِينَ لَهُ ٱلدِّينَ ۗ ٱلْحَمْدُ لِلَّهِ رَبِّ ٱلْعَـٰلَمِينَ

Transliteration huwa l-ḥayu lā ilāha illā huwa fa-id'ʿūhu mukh'liṣīna lahu l-dīna l-ḥamdu lillahi rabbi l-ʿālamīna

Yoruba Òun ni Alààyè. Kò sí ọlọ́hun kan tí ẹ gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo àyàfi Òun. Nítorí náà, ẹ pè É lẹ́ni tí yóò máa fi àfọ̀mọ́-ọkàn (àníyàn mímọ́) ṣe ẹ̀sìn fún Un.Gbogbo ẹyìn ń jẹ́ ti Allāhu, Olúwa gbogbo ẹ̀dá.

Verse 66

۞ قُلْ إِنِّى نُهِيتُ أَنْ أَعْبُدَ ٱلَّذِينَ تَدْعُونَ مِن دُونِ ٱللَّهِ لَمَّا جَآءَنِىَ ٱلْبَيِّنَـٰتُ مِن رَّبِّى وَأُمِرْتُ أَنْ أُسْلِمَ لِرَبِّ ٱلْعَـٰلَمِينَ

Transliteration qul innī nuhītu an aʿbuda alladhīna tadʿūna min dūni l-lahi lammā jāaniya l-bayinātu min rabbī wa-umir'tu an us'lima lirabbi l-ʿālamīna

Yoruba Sọ pé: “Dájúdájú Wọ́n kọ̀ fún mi pé kí n̄g jọ́sìn fún àwọn tí ẹ̀ ń pè lẹ́yìn Allāhu, nígbà tí àwọn ẹ̀rí tó yanjú ti dé bá mi láti ọ̀dọ̀ Olúwa mi, tí wọ́n sì pa mí ní àṣẹ pé kí n̄g juwọ́ jusẹ̀ sílẹ̀ (kí n̄g jẹ́ mùsùlùmí) fún Olúwa gbogbo ẹ̀dá.

Verse 67

هُوَ ٱلَّذِى خَلَقَكُم مِّن تُرَابٍ ثُمَّ مِن نُّطْفَةٍ ثُمَّ مِنْ عَلَقَةٍ ثُمَّ يُخْرِجُكُمْ طِفْلًا ثُمَّ لِتَبْلُغُوٓا۟ أَشُدَّكُمْ ثُمَّ لِتَكُونُوا۟ شُيُوخًا ۚ وَمِنكُم مَّن يُتَوَفَّىٰ مِن قَبْلُ ۖ وَلِتَبْلُغُوٓا۟ أَجَلًا مُّسَمًّى وَلَعَلَّكُمْ تَعْقِلُونَ

Transliteration huwa alladhī khalaqakum min turābin thumma min nuṭ'fatin thumma min ʿalaqatin thumma yukh'rijukum ṭif'lan thumma litablughū ashuddakum thumma litakūnū shuyūkhan waminkum man yutawaffā min qablu walitablughū ajalan musamman walaʿallakum taʿqilūna

Yoruba Òun ni Ẹni tí Ó ṣẹ̀dá yín láti inú erùpẹ̀, lẹ́yìn náà láti inú àtọ̀, lẹ́yìn náà láti inú ẹ̀jẹ̀ dídì, lẹ́yìn náà Ó mu yín jáde ní òpóǹló. Lẹ́yìn náà, (Ó da yín sí) nítorí kí ẹ lè sánn̄gun dópin agbára yín. Lẹ́yìn náà (Ó tún da yín sí) nítorí kí ẹ lè di àgbàlágbà. Ó wà nínú yín ẹni tí A óò ti gba ẹ̀mí rẹ̀ ṣíwájú (ipò àgbà). Àti pé (Ó da yín sí) nítorí kí ẹ lè dàgbà dé gbèdéke àkókò kan àti nítorí kí ẹ lè ṣe làákàyè.

Verse 68

هُوَ ٱلَّذِى يُحْىِۦ وَيُمِيتُ ۖ فَإِذَا قَضَىٰٓ أَمْرًا فَإِنَّمَا يَقُولُ لَهُۥ كُن فَيَكُونُ

Transliteration huwa alladhī yuḥ'yī wayumītu fa-idhā qaḍā amran fa-innamā yaqūlu lahu kun fayakūnu

Yoruba Òun ni Ẹni tí ń sọ ẹ̀dá di alààyè. Ó sì ń sọ ẹ̀dá di òkú. Nígbà tí Ó bá sì pèbùbù kiní kan, Ó kàn máa sọ fún un pé: “Jẹ́ bẹ́ẹ̀.” Ó sì máa jẹ́ bẹ́ẹ̀.

Verse 69

أَلَمْ تَرَ إِلَى ٱلَّذِينَ يُجَـٰدِلُونَ فِىٓ ءَايَـٰتِ ٱللَّهِ أَنَّىٰ يُصْرَفُونَ

Transliteration alam tara ilā alladhīna yujādilūna fī āyāti l-lahi annā yuṣ'rafūna

Yoruba Ṣé o kò wòye sí àwọn tí ń ṣàríyànjiyàn nípa àwọn āyah Allāhu bí wọ́n ṣe ń ṣẹ́rí wọn kúrò níbi òdodo!

Verse 70

ٱلَّذِينَ كَذَّبُوا۟ بِٱلْكِتَـٰبِ وَبِمَآ أَرْسَلْنَا بِهِۦ رُسُلَنَا ۖ فَسَوْفَ يَعْلَمُونَ

Transliteration alladhīna kadhabū bil-kitābi wabimā arsalnā bihi rusulanā fasawfa yaʿlamūna

Yoruba Àwọn tó pe Tírà náà àti ohun tí A fi rán àwọn Òjíṣẹ́ Wa níṣẹ́ ní irọ́, láìpẹ́ wọ́n máa mọ̀.

Verse 71

إِذِ ٱلْأَغْلَـٰلُ فِىٓ أَعْنَـٰقِهِمْ وَٱلسَّلَـٰسِلُ يُسْحَبُونَ

Transliteration idhi l-aghlālu fī aʿnāqihim wal-salāsilu yus'ḥabūna

Yoruba Nígbà tí àwọn sẹ́kẹ́sẹkẹ̀ àti ẹ̀wọ̀n bá wà ní ọrùn wọn, tí wọn yóò fi máa wọ́ wọn

Verse 72

فِى ٱلْحَمِيمِ ثُمَّ فِى ٱلنَّارِ يُسْجَرُونَ

Transliteration fī l-ḥamīmi thumma fī l-nāri yus'jarūna

Yoruba sínú omi tó gbóná parí. Lẹ́yìn náà, wọn yóò fi wọ́n ko Iná.

Verse 73

ثُمَّ قِيلَ لَهُمْ أَيْنَ مَا كُنتُمْ تُشْرِكُونَ

Transliteration thumma qīla lahum ayna mā kuntum tush'rikūna

Yoruba Lẹ́yìn náà, wọ́n máa sọ fún wọn pé: “Ibo ni ohun tí ẹ sọ di òrìṣà wà?”

Verse 74

مِن دُونِ ٱللَّهِ ۖ قَالُوا۟ ضَلُّوا۟ عَنَّا بَل لَّمْ نَكُن نَّدْعُوا۟ مِن قَبْلُ شَيْـًٔا ۚ كَذَٰلِكَ يُضِلُّ ٱللَّهُ ٱلْكَـٰفِرِينَ

Transliteration min dūni l-lahi qālū ḍallū ʿannā bal lam nakun nadʿū min qablu shayan kadhālika yuḍillu l-lahu l-kāfirīna

Yoruba “(Ohun tí ẹ jọ́sìn fún) lẹ́yìn Allāhu (dà)?” Wọ́n á wí pé: “Wọ́n ti di òfò mọ́ wa lọ́wọ́. Bẹ́ẹ̀ tiẹ̀ kọ́, àwa kì í pe n̄ǹkan kan tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀.” Báyẹn ni Allāhu ṣe ń ṣi àwọn aláìgbàgbọ́ lọ́nà.

Verse 75

ذَٰلِكُم بِمَا كُنتُمْ تَفْرَحُونَ فِى ٱلْأَرْضِ بِغَيْرِ ٱلْحَقِّ وَبِمَا كُنتُمْ تَمْرَحُونَ

Transliteration dhālikum bimā kuntum tafraḥūna fī l-arḍi bighayri l-ḥaqi wabimā kuntum tamraḥūna

Yoruba Ìyẹn nítorí pé ẹ̀ ń yọ lórí ilẹ̀ ní ọ̀nà àìtọ́ àti nítorí pé, ẹ̀ ń ṣe fáàrí (lórí àìgbàgbọ́).

Verse 76

ٱدْخُلُوٓا۟ أَبْوَٰبَ جَهَنَّمَ خَـٰلِدِينَ فِيهَا ۖ فَبِئْسَ مَثْوَى ٱلْمُتَكَبِّرِينَ

Transliteration ud'khulū abwāba jahannama khālidīna fīhā fabi'sa mathwā l-mutakabirīna

Yoruba Ẹ wọ àwọn ẹnu ọ̀na iná Jahanamọ; olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀. Ó sì burú ní ibùgbé fún àwọn onígbèéraga.

Verse 77

فَٱصْبِرْ إِنَّ وَعْدَ ٱللَّهِ حَقٌّ ۚ فَإِمَّا نُرِيَنَّكَ بَعْضَ ٱلَّذِى نَعِدُهُمْ أَوْ نَتَوَفَّيَنَّكَ فَإِلَيْنَا يُرْجَعُونَ

Transliteration fa-iṣ'bir inna waʿda l-lahi ḥaqqun fa-immā nuriyannaka baʿḍa alladhī naʿiduhum aw natawaffayannaka fa-ilaynā yur'jaʿūna

Yoruba Nítorí náà, ṣe sùúrù. Dájúdájú àdéhùn Allāhu ni òdodo. Ó ṣeé ṣe kí A fi apá kan èyí tí A ṣe ní ìlérí fún wọn hàn ọ́ tàbí kí A ti gba ẹ̀mí rẹ (ṣíwájú àsìkò náà). Ọ̀dọ̀ Wa kúkú ni wọ́n máa dá wọn padà sí.

Verse 78

وَلَقَدْ أَرْسَلْنَا رُسُلًا مِّن قَبْلِكَ مِنْهُم مَّن قَصَصْنَا عَلَيْكَ وَمِنْهُم مَّن لَّمْ نَقْصُصْ عَلَيْكَ ۗ وَمَا كَانَ لِرَسُولٍ أَن يَأْتِىَ بِـَٔايَةٍ إِلَّا بِإِذْنِ ٱللَّهِ ۚ فَإِذَا جَآءَ أَمْرُ ٱللَّهِ قُضِىَ بِٱلْحَقِّ وَخَسِرَ هُنَالِكَ ٱلْمُبْطِلُونَ

Transliteration walaqad arsalnā rusulan min qablika min'hum man qaṣaṣnā ʿalayka wamin'hum man lam naqṣuṣ ʿalayka wamā kāna lirasūlin an yatiya biāyatin illā bi-idh'ni l-lahi fa-idhā jāa amru l-lahi quḍiya bil-ḥaqi wakhasira hunālika l-mub'ṭilūna

Yoruba Àti pé A kúkú ti rán àwọn Òjísẹ́ níṣẹ́ ṣíwájú rẹ. Àwọn tí A sọ ìtàn wọn fún ọ wà nínú wọn. Àwọn tí A kò sọ ìtàn wọn fún ọ wà nínú wọn. Àti pé kò tọ́ fún Òjísẹ́ kan láti mú àmì kan wá àyàfi pẹ̀lú ìyọ̀ǹda Allāhu. Nígbà tí àṣẹ Allāhu bá sì dé, A máa fi òdodo dájọ́. Àwọn òpùrọ́ sì máa ṣòfò dànù níbẹ̀ yẹn.1

Verse 79

ٱللَّهُ ٱلَّذِى جَعَلَ لَكُمُ ٱلْأَنْعَـٰمَ لِتَرْكَبُوا۟ مِنْهَا وَمِنْهَا تَأْكُلُونَ

Transliteration al-lahu alladhī jaʿala lakumu l-anʿāma litarkabū min'hā wamin'hā takulūna

Yoruba Allāhu ni Ẹni tí Ó dá àwọn ẹran-ọ̀sìn fún yín nítorí kí ẹ lè máa gùn nínú wọn. Ẹ ó sì máa jẹ nínú wọn.

Verse 80

وَلَكُمْ فِيهَا مَنَـٰفِعُ وَلِتَبْلُغُوا۟ عَلَيْهَا حَاجَةً فِى صُدُورِكُمْ وَعَلَيْهَا وَعَلَى ٱلْفُلْكِ تُحْمَلُونَ

Transliteration walakum fīhā manāfiʿu walitablughū ʿalayhā ḥājatan fī ṣudūrikum waʿalayhā waʿalā l-ful'ki tuḥ'malūna

Yoruba Àwọn àǹfààní (mìíràn) wà fún yín lára ẹran-ọ̀sìn. Àti nítorí kí ẹ lè dé ọ̀nà jíjìn tó wà lọ́kàn yín lórí (gígùn) wọ́n (kiri). Ẹ sì ń fi àwọn (ẹran-ọ̀sìn) àti ọkọ̀ ojú-omi gbé àwọn ẹrù.

Verse 81

وَيُرِيكُمْ ءَايَـٰتِهِۦ فَأَىَّ ءَايَـٰتِ ٱللَّهِ تُنكِرُونَ

Transliteration wayurīkum āyātihi fa-ayya āyāti l-lahi tunkirūna

Yoruba (Allāhu) ń fi àwọn àmì Rẹ̀ hàn yín. Nítorí náà, èwo nínú àwọn àmì Allāhu l’ẹ máa takò?1

Verse 82

أَفَلَمْ يَسِيرُوا۟ فِى ٱلْأَرْضِ فَيَنظُرُوا۟ كَيْفَ كَانَ عَـٰقِبَةُ ٱلَّذِينَ مِن قَبْلِهِمْ ۚ كَانُوٓا۟ أَكْثَرَ مِنْهُمْ وَأَشَدَّ قُوَّةً وَءَاثَارًا فِى ٱلْأَرْضِ فَمَآ أَغْنَىٰ عَنْهُم مَّا كَانُوا۟ يَكْسِبُونَ

Transliteration afalam yasīrū fī l-arḍi fayanẓurū kayfa kāna ʿāqibatu alladhīna min qablihim kānū akthara min'hum wa-ashadda quwwatan waāthāran fī l-arḍi famā aghnā ʿanhum mā kānū yaksibūna

Yoruba Ṣé wọn kò rìn kiri lórí ilẹ̀ kí wọ́n wo bí ìkángun àwọn tó ṣíwájú wọn ṣe rí? Wọ́n pọ̀ (ní òǹkà) jù wọ́n lọ. Wọ́n ní agbára jù wọ́n lọ. Wọ́n sì lo ilẹ̀(fún oko dídá jù wọ́n lọ). Síbẹ̀síbẹ̀ ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́ kò rọ̀ wọ́n lọ́rọ̀ (níbi ìyà).

Verse 83

فَلَمَّا جَآءَتْهُمْ رُسُلُهُم بِٱلْبَيِّنَـٰتِ فَرِحُوا۟ بِمَا عِندَهُم مِّنَ ٱلْعِلْمِ وَحَاقَ بِهِم مَّا كَانُوا۟ بِهِۦ يَسْتَهْزِءُونَ

Transliteration falammā jāathum rusuluhum bil-bayināti fariḥū bimā ʿindahum mina l-ʿil'mi waḥāqa bihim mā kānū bihi yastahziūna

Yoruba Nígbà tí àwọn Òjíṣẹ́ wọn mú àwọn ẹ̀rí tó yanjú wá bá wọn, wọ́n yọ àyọ̀pọ̀rọ́ nítorí ohun tó wà lọ́dọ̀ wọn nínú ìmọ̀ (ayé). Ohun tí wọ́n sì ń fi ṣe yẹ̀yẹ́ sì dìyà tó yí wọn po.

Verse 84

فَلَمَّا رَأَوْا۟ بَأْسَنَا قَالُوٓا۟ ءَامَنَّا بِٱللَّهِ وَحْدَهُۥ وَكَفَرْنَا بِمَا كُنَّا بِهِۦ مُشْرِكِينَ

Transliteration falammā ra-aw basanā qālū āmannā bil-lahi waḥdahu wakafarnā bimā kunnā bihi mush'rikīna

Yoruba Nígbà tí wọ́n rí ìyà Wa, wọ́n wí pé: “A gbàgbọ́ nínú Allāhu nìkan ṣoṣo. A sì lòdì sí n̄ǹkan tí a sọ di akẹgbẹ́ fún Un.”

Verse 85

فَلَمْ يَكُ يَنفَعُهُمْ إِيمَـٰنُهُمْ لَمَّا رَأَوْا۟ بَأْسَنَا ۖ سُنَّتَ ٱللَّهِ ٱلَّتِى قَدْ خَلَتْ فِى عِبَادِهِۦ ۖ وَخَسِرَ هُنَالِكَ ٱلْكَـٰفِرُونَ

Transliteration falam yaku yanfaʿuhum īmānuhum lammā ra-aw basanā sunnata l-lahi allatī qad khalat fī ʿibādihi wakhasira hunālika l-kāfirūna

Yoruba Ìgbàgbọ́ wọn kò sì ṣe wọ́n ní àǹfààní nígbà tí wọ́n rí ìyà Wa. Ìṣe Allāhu, èyí tí ó ti ṣẹlẹ̀ ṣíwájú sí àwọn ẹrú Rẹ̀ (ni èyí). Àwọn aláìgbàgbọ́ sì ṣòfò dànù níbẹ̀ yẹn.

Read Surah Ghafir in another language

All languages

All 114 surahs in Yoruba: the Qur’an in Yoruba.

Learn it in MyDugsi

Yoruba translation: Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni, from Quran.com. Transliteration: Quran.com. Recitation: Mishary Alafasy, from EveryAyah.com. MyDugsi is a learning aid, not a replacement for a qualified teacher.