Surah Al-Qalam in Yoruba: translation and audio
Surah 68 · القلم · The Pen · 52 verses
Surah Al-Qalam verse by verse: the Arabic with a recitation you can repeat, the transliteration, and the Yoruba translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni. For the meaning of every word, see Surah Al-Qalam word by word in English.
Verse 1
نٓ ۚ وَٱلْقَلَمِ وَمَا يَسْطُرُونَ
Transliteration noon wal-qalami wamā yasṭurūna
Yoruba Nūn. (Allāhu ló mọ ohun tí Ó gbàlérò pẹ̀lú háràfí náà.)Allāhu fi gègé ìkọ̀wé àti ohun tí àwọn mọlāika ń kọ sílẹ̀ búra.
Verse 2
مَآ أَنتَ بِنِعْمَةِ رَبِّكَ بِمَجْنُونٍ
Transliteration mā anta biniʿ'mati rabbika bimajnūnin
Yoruba Ìwọ kì í ṣe wèrè nípa ìdẹ̀ra Olúwa rẹ.
Verse 3
وَإِنَّ لَكَ لَأَجْرًا غَيْرَ مَمْنُونٍ
Transliteration wa-inna laka la-ajran ghayra mamnūnin
Yoruba Àti pé dájúdájú ẹ̀san tí kò níí dáwọ́ dúró ti wà fún ọ.
Verse 4
وَإِنَّكَ لَعَلَىٰ خُلُقٍ عَظِيمٍ
Transliteration wa-innaka laʿalā khuluqin ʿaẓīmin
Yoruba Dájúdájú ìwọ sì wà lórí ìwà ńlá (ìwà alápọ̀n-ọ́nlé).
Verse 5
فَسَتُبْصِرُ وَيُبْصِرُونَ
Transliteration fasatub'ṣiru wayub'ṣirūna
Yoruba Láìpẹ́ ìwọ yóò rí i, àwọn náà yó sì rí i;
Verse 6
بِأَييِّكُمُ ٱلْمَفْتُونُ
Transliteration bi-ayyikumu l-maftūnu
Yoruba èwo nínú yín ni aládàn-ánwò (wèrè)?
Verse 7
إِنَّ رَبَّكَ هُوَ أَعْلَمُ بِمَن ضَلَّ عَن سَبِيلِهِۦ وَهُوَ أَعْلَمُ بِٱلْمُهْتَدِينَ
Transliteration inna rabbaka huwa aʿlamu biman ḍalla ʿan sabīlihi wahuwa aʿlamu bil-muh'tadīna
Yoruba Dájúdájú Olúwa rẹ, Ó nímọ̀ jùlọ nípa ẹni tó ṣìnà kúrò lójú ọ̀nà Rẹ̀. Ó sì nímọ̀ jùlọ nípa àwọn olùmọ̀nà.
Verse 8
فَلَا تُطِعِ ٱلْمُكَذِّبِينَ
Transliteration falā tuṭiʿi l-mukadhibīna
Yoruba Nítorí náà, má ṣe tẹ̀lé àwọn olùpe-òdodo-nírọ́.
Verse 9
وَدُّوا۟ لَوْ تُدْهِنُ فَيُدْهِنُونَ
Transliteration waddū law tud'hinu fayud'hinūna
Yoruba Àti pé wọ́n fẹ́ kí o dẹwọ́, kí àwọn náà sì dẹwọ́.
Verse 10
وَلَا تُطِعْ كُلَّ حَلَّافٍ مَّهِينٍ
Transliteration walā tuṭiʿ kulla ḥallāfin mahīnin
Yoruba Má ṣe tẹ̀lé gbogbo ẹni tí ìbúra rẹ̀ pọ̀, ẹni yẹpẹrẹ,
Verse 11
هَمَّازٍ مَّشَّآءٍۭ بِنَمِيمٍ
Transliteration hammāzin mashāin binamīmin
Yoruba abúni, alárìnká tó ń sòfófó kiri,
Verse 12
مَّنَّاعٍ لِّلْخَيْرِ مُعْتَدٍ أَثِيمٍ
Transliteration mannāʿin lil'khayri muʿ'tadin athīmin
Yoruba olùdènà iṣẹ́ rere, alákọyọ, ẹlẹ́ṣẹ̀,
Verse 13
عُتُلٍّۭ بَعْدَ ذَٰلِكَ زَنِيمٍ
Transliteration ʿutullin baʿda dhālika zanīmin
Yoruba ọ̀dájú. Lẹ́yìn ìyẹn, ògbólógbòó ẹni ibi (àsáwọ̀ ọmọ zina) ni.
Verse 14
أَن كَانَ ذَا مَالٍ وَبَنِينَ
Transliteration an kāna dhā mālin wabanīna
Yoruba Nítorí pé ó ní dúkìá àti àwọn ọmọkùnrin,
Verse 15
إِذَا تُتْلَىٰ عَلَيْهِ ءَايَـٰتُنَا قَالَ أَسَـٰطِيرُ ٱلْأَوَّلِينَ
Transliteration idhā tut'lā ʿalayhi āyātunā qāla asāṭīru l-awalīna
Yoruba nígbà tí wọ́n bá ń ké àwọn āyah Wa fún un, ó máa wí pé: “Àkọsílẹ̀ àlọ́ àwọn ẹni àkọ́kọ́ (nìwọ̀nyí)”.
Verse 16
سَنَسِمُهُۥ عَلَى ٱلْخُرْطُومِ
Transliteration sanasimuhu ʿalā l-khur'ṭūmi
Yoruba A máa fi àmì sí i ní góńgórí imú.
Verse 17
إِنَّا بَلَوْنَـٰهُمْ كَمَا بَلَوْنَآ أَصْحَـٰبَ ٱلْجَنَّةِ إِذْ أَقْسَمُوا۟ لَيَصْرِمُنَّهَا مُصْبِحِينَ
Transliteration innā balawnāhum kamā balawnā aṣḥāba l-janati idh aqsamū layaṣrimunnahā muṣ'biḥīna
Yoruba Dájúdájú Àwa dán wọn wò gẹ́gẹ́ bí A ṣe dán àwọn ọlọ́gbà wò nígbà tí wọ́n búra pé, dájúdájú àwọn yóò ká gbogbo èso ọgbà náà ní òwúrọ̀ kùtùkùtù.
Verse 18
وَلَا يَسْتَثْنُونَ
Transliteration walā yastathnūna
Yoruba Wọn kò sì ṣe àyàfi pé, “tí Allāhu bá fẹ́”.
Verse 19
فَطَافَ عَلَيْهَا طَآئِفٌ مِّن رَّبِّكَ وَهُمْ نَآئِمُونَ
Transliteration faṭāfa ʿalayhā ṭāifun min rabbika wahum nāimūna
Yoruba Àdánwò tó ń yí n̄ǹkan po láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ sì yí ọgbà náà po, nígbà tí wọ́n sùn lọ.
Verse 20
فَأَصْبَحَتْ كَٱلصَّرِيمِ
Transliteration fa-aṣbaḥat kal-ṣarīmi
Yoruba Ó sì dà bí oko àgédànù (tí wọ́n ti résun).
Verse 21
فَتَنَادَوْا۟ مُصْبِحِينَ
Transliteration fatanādaw muṣ'biḥīna
Yoruba Wọ́n ń pera wọn ní òwúrọ̀ kùtùkùtù
Verse 22
أَنِ ٱغْدُوا۟ عَلَىٰ حَرْثِكُمْ إِن كُنتُمْ صَـٰرِمِينَ
Transliteration ani igh'dū ʿalā ḥarthikum in kuntum ṣārimīna
Yoruba pé ẹ jí lọ sí oko yín tí ẹ bá fẹ́ ká èso.
Verse 23
فَٱنطَلَقُوا۟ وَهُمْ يَتَخَـٰفَتُونَ
Transliteration fa-inṭalaqū wahum yatakhāfatūna
Yoruba Wọ́n lọ, wọ́n sì ń fi ohùn jẹ́ẹ́jẹ́ bára wọn sọ̀rọ̀
Verse 24
أَن لَّا يَدْخُلَنَّهَا ٱلْيَوْمَ عَلَيْكُم مِّسْكِينٌ
Transliteration an lā yadkhulannahā l-yawma ʿalaykum mis'kīnun
Yoruba pé ní òní mẹ̀kúnnù kan kò gbọdọ̀ wọnú rẹ̀ wá ba yín.
Verse 25
وَغَدَوْا۟ عَلَىٰ حَرْدٍ قَـٰدِرِينَ
Transliteration waghadaw ʿalā ḥardin qādirīna
Yoruba Wọ́n jí lọ (sí oko wọn) lórí èrò-ọkàn kan (pé) àwọn lágbára.
Verse 26
فَلَمَّا رَأَوْهَا قَالُوٓا۟ إِنَّا لَضَآلُّونَ
Transliteration falammā ra-awhā qālū innā laḍāllūna
Yoruba Nígbà tí wọ́n rí i, wọ́n wí pé: “Dájúdájú àwa ti ṣìnà.
Verse 27
بَلْ نَحْنُ مَحْرُومُونَ
Transliteration bal naḥnu maḥrūmūna
Yoruba Rárá o, wọ́n ṣe ìkórè oko léèwọ̀ fún wa ni.”
Verse 28
قَالَ أَوْسَطُهُمْ أَلَمْ أَقُل لَّكُمْ لَوْلَا تُسَبِّحُونَ
Transliteration qāla awsaṭuhum alam aqul lakum lawlā tusabbiḥūna
Yoruba Ẹni tó dúró déédé jùlọ nínú wọn sọ pé: “Ṣé èmi kò sọ fún yín pé ẹ̀yin kò ṣe ṣàfọ̀mọ́ fún Allāhu (pé “a máa kórè oko wa, ’in ṣā ’Allāhu.)”?
Verse 29
قَالُوا۟ سُبْحَـٰنَ رَبِّنَآ إِنَّا كُنَّا ظَـٰلِمِينَ
Transliteration qālū sub'ḥāna rabbinā innā kunnā ẓālimīna
Yoruba Wọ́n wí pé: “Mímọ́ ni fún Olúwa wa, dájúdájú àwa jẹ́ alábòsí.”
Verse 30
فَأَقْبَلَ بَعْضُهُمْ عَلَىٰ بَعْضٍ يَتَلَـٰوَمُونَ
Transliteration fa-aqbala baʿḍuhum ʿalā baʿḍin yatalāwamūna
Yoruba Apá kan wọn kọjú sí apá kan; wọ́n sì ń dára wọn lẹ́bi.
Verse 31
قَالُوا۟ يَـٰوَيْلَنَآ إِنَّا كُنَّا طَـٰغِينَ
Transliteration qālū yāwaylanā innā kunnā ṭāghīna
Yoruba Wọ́n wí pé: “Ègbé wa ò! Dájúdájú àwa jẹ́ olùtayọ-ẹnu ààlà.
Verse 32
عَسَىٰ رَبُّنَآ أَن يُبْدِلَنَا خَيْرًا مِّنْهَآ إِنَّآ إِلَىٰ رَبِّنَا رَٰغِبُونَ
Transliteration ʿasā rabbunā an yub'dilanā khayran min'hā innā ilā rabbinā rāghibūna
Yoruba Ó ṣeé ṣe kí Olúwa wa fi èyí tó dára ju èyí lọ pààrọ̀ rẹ̀ fún wa. Dájúdájú ọ̀dọ̀ Olúwa wa ni àwa ń rokàn oore sí.”
Verse 33
كَذَٰلِكَ ٱلْعَذَابُ ۖ وَلَعَذَابُ ٱلْـَٔاخِرَةِ أَكْبَرُ ۚ لَوْ كَانُوا۟ يَعْلَمُونَ
Transliteration kadhālika l-ʿadhābu walaʿadhābu l-ākhirati akbaru law kānū yaʿlamūna
Yoruba Báyẹn ni ìyà náà ṣe rí (fún wọn). Ìyà ọ̀run sì tóbi jùlọ, tí ó bá jẹ́ pé wọ́n mọ̀.
Verse 34
إِنَّ لِلْمُتَّقِينَ عِندَ رَبِّهِمْ جَنَّـٰتِ ٱلنَّعِيمِ
Transliteration inna lil'muttaqīna ʿinda rabbihim jannāti l-naʿīmi
Yoruba Dájúdájú àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra wà fún àwọn olùbẹ̀rù Allāhu lọ́dọ̀ Olúwa wọn.
Verse 35
أَفَنَجْعَلُ ٱلْمُسْلِمِينَ كَٱلْمُجْرِمِينَ
Transliteration afanajʿalu l-mus'limīna kal-muj'rimīna
Yoruba Ṣé A máa ṣe àwọn mùsùlùmí bí (A ṣe máa ṣe) àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ bí?
Verse 36
مَا لَكُمْ كَيْفَ تَحْكُمُونَ
Transliteration mā lakum kayfa taḥkumūna
Yoruba Kí l’ó ń ṣe yín tí ẹ fi ń dájọ́ báyìí ná?1
Verse 37
أَمْ لَكُمْ كِتَـٰبٌ فِيهِ تَدْرُسُونَ
Transliteration am lakum kitābun fīhi tadrusūna
Yoruba Tàbí tírà kan wà fún yín tí ẹ̀ ń kẹ́kọ̀ọ́ nínú rẹ̀
Verse 38
إِنَّ لَكُمْ فِيهِ لَمَا تَخَيَّرُونَ
Transliteration inna lakum fīhi lamā takhayyarūna
Yoruba pé dájúdájú ẹ̀yin lẹ ni ohun tí ẹ bá ń ṣà lẹ́ṣà nínú ìdájọ́?
Verse 39
أَمْ لَكُمْ أَيْمَـٰنٌ عَلَيْنَا بَـٰلِغَةٌ إِلَىٰ يَوْمِ ٱلْقِيَـٰمَةِ ۙ إِنَّ لَكُمْ لَمَا تَحْكُمُونَ
Transliteration am lakum aymānun ʿalaynā bālighatun ilā yawmi l-qiyāmati inna lakum lamā taḥkumūna
Yoruba Ǹjẹ́ ẹ ni àwọn àdéhùn kan lọ́dọ̀ wa tí ó máa wà títí di Ọjọ́ Àjíǹde pé: “Dájúdájú tiyín ni ìdájọ́ tí ẹ bá ti mú wá.”?
Verse 40
سَلْهُمْ أَيُّهُم بِذَٰلِكَ زَعِيمٌ
Transliteration salhum ayyuhum bidhālika zaʿīmun
Yoruba Bi wọ́n léèrè wò pé èwo nínú wọn l’ó lè fọwọ́ ìyẹn sọ̀yà!
Verse 41
أَمْ لَهُمْ شُرَكَآءُ فَلْيَأْتُوا۟ بِشُرَكَآئِهِمْ إِن كَانُوا۟ صَـٰدِقِينَ
Transliteration am lahum shurakāu falyatū bishurakāihim in kānū ṣādiqīna
Yoruba Tàbí wọ́n ní (àwọn òrìṣà kan) tí wọ́n jẹ́ akẹgbẹ́ Wa? Kí wọ́n mú àwọn òrìṣà wọn wá nígbà náà tí wọ́n bá jẹ́ olódodo.
Verse 42
يَوْمَ يُكْشَفُ عَن سَاقٍ وَيُدْعَوْنَ إِلَى ٱلسُّجُودِ فَلَا يَسْتَطِيعُونَ
Transliteration yawma yuk'shafu ʿan sāqin wayud'ʿawna ilā l-sujūdi falā yastaṭīʿūna
Yoruba Ní ọjọ́ tí A máa ṣí ojúgun sílẹ̀, A sì máa pè wọ́n síbi ìforíkanlẹ̀, wọn kò sì níí lè ṣe é.
Verse 43
خَـٰشِعَةً أَبْصَـٰرُهُمْ تَرْهَقُهُمْ ذِلَّةٌ ۖ وَقَدْ كَانُوا۟ يُدْعَوْنَ إِلَى ٱلسُّجُودِ وَهُمْ سَـٰلِمُونَ
Transliteration khāshiʿatan abṣāruhum tarhaquhum dhillatun waqad kānū yud'ʿawna ilā l-sujūdi wahum sālimūna
Yoruba Ojú wọn yóò wálẹ̀. Ìyẹpẹrẹ máa bò wọ́n mọ́lẹ̀. Wọ́n kúkú ti pè wọ́n síbi ìforíkanlẹ̀ nígbà tí wọ́n ní àlàáfíà (wọn kò sì kírun).
Verse 44
فَذَرْنِى وَمَن يُكَذِّبُ بِهَـٰذَا ٱلْحَدِيثِ ۖ سَنَسْتَدْرِجُهُم مِّنْ حَيْثُ لَا يَعْلَمُونَ
Transliteration fadharnī waman yukadhibu bihādhā l-ḥadīthi sanastadrijuhum min ḥaythu lā yaʿlamūna
Yoruba Nítorí náà, fi Èmi àti ẹni tó ń pe ọ̀rọ̀ yìí ní irọ́ sílẹ̀. A óò máa dẹ wọ́n lẹ́kẹ láti jẹ wọ́n níyà ní àyè tí wọn kò mọ̀.
Verse 45
وَأُمْلِى لَهُمْ ۚ إِنَّ كَيْدِى مَتِينٌ
Transliteration wa-um'lī lahum inna kaydī matīnun
Yoruba Mò ń lọ́ra fún wọn ni. Dájúdájú ète Mi lágbára.1
Verse 46
أَمْ تَسْـَٔلُهُمْ أَجْرًا فَهُم مِّن مَّغْرَمٍ مُّثْقَلُونَ
Transliteration am tasaluhum ajran fahum min maghramin muth'qalūna
Yoruba Tàbí ò ń bèèrè owó-ọ̀yà kan lọ́wọ́ wọn, ni gbèsè fi wọ̀ wọ́n lọ́rùn?
Verse 47
أَمْ عِندَهُمُ ٱلْغَيْبُ فَهُمْ يَكْتُبُونَ
Transliteration am ʿindahumu l-ghaybu fahum yaktubūna
Yoruba Tàbí lọ́dọ̀ wọn ni (wàláà) ìkọ̀kọ̀ wà ni wọ́n bá ń kọ ọ́ (síta)?
Verse 48
فَٱصْبِرْ لِحُكْمِ رَبِّكَ وَلَا تَكُن كَصَاحِبِ ٱلْحُوتِ إِذْ نَادَىٰ وَهُوَ مَكْظُومٌ
Transliteration fa-iṣ'bir liḥuk'mi rabbika walā takun kaṣāḥibi l-ḥūti idh nādā wahuwa makẓūmun
Yoruba Nítorí náà, ṣe sùúrù fún ìdájọ́ Olúwa rẹ. Kí ìwọ má sì ṣe dà bí ẹlẹ́ja (ìyẹn, Ànábì Yūnus) nígbà tí ó pe (Allāhu) pẹ̀lú ìbànújẹ́.
Verse 49
لَّوْلَآ أَن تَدَٰرَكَهُۥ نِعْمَةٌ مِّن رَّبِّهِۦ لَنُبِذَ بِٱلْعَرَآءِ وَهُوَ مَذْمُومٌ
Transliteration lawlā an tadārakahu niʿ'matun min rabbihi lanubidha bil-ʿarāi wahuwa madhmūmun
Yoruba Tí kò bá jẹ́ pé ìkẹ́ kan láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ̀ lé e bá, wọn ìbá jù ú sórí ilẹ̀ gban̄sasa (láti inú ẹja) ní ẹni-èébú.
Verse 50
فَٱجْتَبَـٰهُ رَبُّهُۥ فَجَعَلَهُۥ مِنَ ٱلصَّـٰلِحِينَ
Transliteration fa-ij'tabāhu rabbuhu fajaʿalahu mina l-ṣāliḥīna
Yoruba Nítorí náà, Olúwa rẹ̀ ṣà á lẹ́ṣà. Ó sì ṣe é ní ara àwọn ẹni rere.
Verse 51
وَإِن يَكَادُ ٱلَّذِينَ كَفَرُوا۟ لَيُزْلِقُونَكَ بِأَبْصَـٰرِهِمْ لَمَّا سَمِعُوا۟ ٱلذِّكْرَ وَيَقُولُونَ إِنَّهُۥ لَمَجْنُونٌ
Transliteration wa-in yakādu alladhīna kafarū layuz'liqūnaka bi-abṣārihim lammā samiʿū l-dhik'ra wayaqūlūna innahu lamajnūnun
Yoruba Àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ fẹ́ẹ̀ fi ojú wọn gbé ọ ṣubú nígbà tí wọ́n gbọ́ ìrántí náà. Wọ́n sì ń wí pé: “Dájúdájú wèrè mà ni.”
Verse 52
وَمَا هُوَ إِلَّا ذِكْرٌ لِّلْعَـٰلَمِينَ
Transliteration wamā huwa illā dhik'run lil'ʿālamīna
Yoruba Kí sì ni al-Ƙur’ān bí kò ṣe ìrántí fún gbogbo ẹ̀dá.
Read Surah Al-Qalam in another language
- English (word by word)
- Albanian
- Amazigh
- Amharic
- Assamese
- Azerbaijani
- Bambara
- Bangla
- Bosnian
- Bulgarian
- Chechen
- Chinese
- Czech
- Dari
- Dhivehi
- Dutch
- Finnish
- French
- German
- Gujarati
- Hausa
- Hebrew
- Hindi
- Indonesian
- Italian
- Japanese
- Kannada
- Kazakh
- Khmer
- Kinyarwanda
- Korean
- Kurdish
- Luganda
- Malay
- Malayalam
- Maranao
- Marathi
- Nepali
- Norwegian
- Oromo
- Pashto
- Persian
- Polish
- Portuguese
- Romanian
- Russian
- Sindhi
- Sinhala
- Somali
- Spanish
- Swahili
- Swedish
- Tagalog
- Tajik
- Tamil
- Tatar
- Telugu
- Thai
- Turkish
- Ukrainian
- Urdu
- Uyghur
- Uzbek
- Vietnamese
- Yao
All 114 surahs in Yoruba: the Qur’an in Yoruba.
Yoruba translation: Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni, from Quran.com. Transliteration: Quran.com. Recitation: Mishary Alafasy, from EveryAyah.com. MyDugsi is a learning aid, not a replacement for a qualified teacher.