Surah Al-Hajj in Yoruba: translation and audio
Surah 22 · الحج · The Pilgrimage · 78 verses
Surah Al-Hajj verse by verse: the Arabic with a recitation you can repeat, the transliteration, and the Yoruba translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni. For the meaning of every word, see Surah Al-Hajj word by word in English.
Verse 1
يَـٰٓأَيُّهَا ٱلنَّاسُ ٱتَّقُوا۟ رَبَّكُمْ ۚ إِنَّ زَلْزَلَةَ ٱلسَّاعَةِ شَىْءٌ عَظِيمٌ
Transliteration yāayyuhā l-nāsu ittaqū rabbakum inna zalzalata l-sāʿati shayon ʿaẓīmun
Yoruba Ẹ̀yin ènìyàn, ẹ bẹ̀rù Olúwa yín. Dájúdájú ìmì tìtì Àkókò náà, n̄ǹkan ńlá ni.
Verse 2
يَوْمَ تَرَوْنَهَا تَذْهَلُ كُلُّ مُرْضِعَةٍ عَمَّآ أَرْضَعَتْ وَتَضَعُ كُلُّ ذَاتِ حَمْلٍ حَمْلَهَا وَتَرَى ٱلنَّاسَ سُكَـٰرَىٰ وَمَا هُم بِسُكَـٰرَىٰ وَلَـٰكِنَّ عَذَابَ ٱللَّهِ شَدِيدٌ
Transliteration yawma tarawnahā tadhhalu kullu mur'ḍiʿatin ʿammā arḍaʿat wataḍaʿu kullu dhāti ḥamlin ḥamlahā watarā l-nāsa sukārā wamā hum bisukārā walākinna ʿadhāba l-lahi shadīdun
Yoruba (Àkókò náà ni) ọjọ́ tí ẹ máa rí i tí gbogbo obìnrin tó ń fún ọmọ lọ́mú mu yóò gbàgbé ọmọ tí ó ń fún lọ́mú àti pé gbogbo aboyún yó sì máa bí oyún wọn. Ìwọ yó sì rí àwọn ènìyàn tí ọtí yóò máa pa wọ́n. Ọtí kò sì pa wọ́n, ṣùgbọ́n ìyà Allāhu (tó) le (ló fà á).
Verse 3
وَمِنَ ٱلنَّاسِ مَن يُجَـٰدِلُ فِى ٱللَّهِ بِغَيْرِ عِلْمٍ وَيَتَّبِعُ كُلَّ شَيْطَـٰنٍ مَّرِيدٍ
Transliteration wamina l-nāsi man yujādilu fī l-lahi bighayri ʿil'min wayattabiʿu kulla shayṭānin marīdin
Yoruba Ó sì ń bẹ nínú àwọn ènìyàn ẹni tó ń jiyàn nípa (ẹ̀sìn) Allāhu láì ní ìmọ̀. Ó sì ń tẹ̀lé gbogbo èṣù olórí kunkun.
Verse 4
كُتِبَ عَلَيْهِ أَنَّهُۥ مَن تَوَلَّاهُ فَأَنَّهُۥ يُضِلُّهُۥ وَيَهْدِيهِ إِلَىٰ عَذَابِ ٱلسَّعِيرِ
Transliteration kutiba ʿalayhi annahu man tawallāhu fa-annahu yuḍilluhu wayahdīhi ilā ʿadhābi l-saʿīri
Yoruba Wọ́n kọ ọ́ lé (Èṣù) lórí pé dájúdájú ẹnikẹ́ni tí ó bá tẹ̀lé e, ó máa ṣì í lọ́nà. Ó sì máa tọ́ ọ sí ọ̀nà ìyà Iná tó ń jo.
Verse 5
يَـٰٓأَيُّهَا ٱلنَّاسُ إِن كُنتُمْ فِى رَيْبٍ مِّنَ ٱلْبَعْثِ فَإِنَّا خَلَقْنَـٰكُم مِّن تُرَابٍ ثُمَّ مِن نُّطْفَةٍ ثُمَّ مِنْ عَلَقَةٍ ثُمَّ مِن مُّضْغَةٍ مُّخَلَّقَةٍ وَغَيْرِ مُخَلَّقَةٍ لِّنُبَيِّنَ لَكُمْ ۚ وَنُقِرُّ فِى ٱلْأَرْحَامِ مَا نَشَآءُ إِلَىٰٓ أَجَلٍ مُّسَمًّى ثُمَّ نُخْرِجُكُمْ طِفْلًا ثُمَّ لِتَبْلُغُوٓا۟ أَشُدَّكُمْ ۖ وَمِنكُم مَّن يُتَوَفَّىٰ وَمِنكُم مَّن يُرَدُّ إِلَىٰٓ أَرْذَلِ ٱلْعُمُرِ لِكَيْلَا يَعْلَمَ مِنۢ بَعْدِ عِلْمٍ شَيْـًٔا ۚ وَتَرَى ٱلْأَرْضَ هَامِدَةً فَإِذَآ أَنزَلْنَا عَلَيْهَا ٱلْمَآءَ ٱهْتَزَّتْ وَرَبَتْ وَأَنۢبَتَتْ مِن كُلِّ زَوْجٍۭ بَهِيجٍ
Transliteration yāayyuhā l-nāsu in kuntum fī raybin mina l-baʿthi fa-innā khalaqnākum min turābin thumma min nuṭ'fatin thumma min ʿalaqatin thumma min muḍ'ghatin mukhallaqatin waghayri mukhallaqatin linubayyina lakum wanuqirru fī l-arḥāmi mā nashāu ilā ajalin musamman thumma nukh'rijukum ṭif'lan thumma litablughū ashuddakum waminkum man yutawaffā waminkum man yuraddu ilā ardhali l-ʿumuri likaylā yaʿlama min baʿdi ʿil'min shayan watarā l-arḍa hāmidatan fa-idhā anzalnā ʿalayhā l-māa ih'tazzat warabat wa-anbatat min kulli zawjin bahījin
Yoruba Ẹ̀yin ènìyàn, tí ẹ bá wà nínú iyèméjì nípa àjíǹde, dájúdájú Àwa ṣẹ̀dá yín láti inú erùpẹ̀, lẹ́yìn náà láti inú àtọ̀, lẹ́yìn náà láti inú ẹ̀jẹ̀ dídì, lẹ́yìn náà láti inú bááṣí ẹran tí ó pé ní ẹ̀dá àti èyí tí kò pé ní ẹ̀dá nítorí kí A lè ṣàlàyé (agbára Wa) fún yín. A sì ń mú ohun tí A bá fẹ́ dúró sínú àpò ìbímọ títí di gbèdéke àkókò kan. Lẹ́yìn náà, A óò mu yín jáde ní òpóǹló. Lẹ́yìn náà, (ẹ óò máa ṣẹ̀mí lọ) nítorí kí ẹ lè sánn̄gun dópin agbára yín. Ẹni tí wọ́n máa pa (ní kékeré) wà nínú yín. Ó sì wà nínú yín ẹni tí wọ́n máa dá (ìṣẹ̀mí) rẹ̀ sí di àsìkò ogbó kùjọ́kùjọ́ nítorí kí ó má lè mọ́ n̄ǹkan kan mọ́ lẹ́yìn tí ó ti mọ̀ ọ́n. Àti pé o máa rí ilẹ̀ ní gbígbẹ. Nígbà tí A bá sì sọ òjò kalẹ̀ lé e lórí, ó máa yíra padà. Ó máa gbèrú. Ó sì máa mú gbogbo oríṣiríṣi irúgbìn tó dára jáde.
Verse 6
ذَٰلِكَ بِأَنَّ ٱللَّهَ هُوَ ٱلْحَقُّ وَأَنَّهُۥ يُحْىِ ٱلْمَوْتَىٰ وَأَنَّهُۥ عَلَىٰ كُلِّ شَىْءٍ قَدِيرٌ
Transliteration dhālika bi-anna l-laha huwa l-ḥaqu wa-annahu yuḥ'yī l-mawtā wa-annahu ʿalā kulli shayin qadīrun
Yoruba Ìyẹn (rí bẹ́ẹ̀) nítorí pé dájúdájú Allāhu, Òun ni Òdodo. Dájúdájú Òun l’Ó ń sọ àwọn òkú di alààyè. Dájúdájú Òun sì ni Alágbára lórí gbogbo n̄ǹkan.
Verse 7
وَأَنَّ ٱلسَّاعَةَ ءَاتِيَةٌ لَّا رَيْبَ فِيهَا وَأَنَّ ٱللَّهَ يَبْعَثُ مَن فِى ٱلْقُبُورِ
Transliteration wa-anna l-sāʿata ātiyatun lā rayba fīhā wa-anna l-laha yabʿathu man fī l-qubūri
Yoruba Àti pé dájúdájú Àkókò náà ń bọ̀. Kò sí iyèméjì nínú rẹ̀. Dájúdájú Allāhu yóò gbé àwọn tó ń bẹ nínú sàréè dìde.
Verse 8
وَمِنَ ٱلنَّاسِ مَن يُجَـٰدِلُ فِى ٱللَّهِ بِغَيْرِ عِلْمٍ وَلَا هُدًى وَلَا كِتَـٰبٍ مُّنِيرٍ
Transliteration wamina l-nāsi man yujādilu fī l-lahi bighayri ʿil'min walā hudan walā kitābin munīrin
Yoruba Ó ń bẹ nínú àwọn ènìyàn ẹni tó ń jiyàn nípa (ẹ̀sìn) Allāhu láì ní ìmọ̀ (al-Ƙur’ān) àti ìmọ̀nà (sunnah Ànábì) àti tírà (onímọ̀-ẹ̀sìn) tó ń tan ìmọ́lẹ̀ (sí ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn).
Verse 9
ثَانِىَ عِطْفِهِۦ لِيُضِلَّ عَن سَبِيلِ ٱللَّهِ ۖ لَهُۥ فِى ٱلدُّنْيَا خِزْىٌ ۖ وَنُذِيقُهُۥ يَوْمَ ٱلْقِيَـٰمَةِ عَذَابَ ٱلْحَرِيقِ
Transliteration thāniya ʿiṭ'fihi liyuḍilla ʿan sabīli l-lahi lahu fī l-dun'yā khiz'yun wanudhīquhu yawma l-qiyāmati ʿadhāba l-ḥarīqi
Yoruba Ó ń ṣègbéraga (sí òdodo, ó ń gbúnrí kúrò níbi òdodo) nítorí kí ó lè kó ìṣìnà bá àwọn ènìyàn lójú ọ̀nà (ẹ̀sìn) Allāhu. Àbùkù ń bẹ fún un nílé ayé. Ní Ọjọ́ Àjíǹde, A sì máa fún un ní ìyà Iná jónijóni tọ́ wò.
Verse 10
ذَٰلِكَ بِمَا قَدَّمَتْ يَدَاكَ وَأَنَّ ٱللَّهَ لَيْسَ بِظَلَّـٰمٍ لِّلْعَبِيدِ
Transliteration dhālika bimā qaddamat yadāka wa-anna l-laha laysa biẓallāmin lil'ʿabīdi
Yoruba Ìyẹn (rí bẹ́ẹ̀) nítorí ohun tí ọwọ́ rẹ̀ tì síwájú. Dájúdájú Allāhu kò níí ṣàbòsí sí àwọn ẹrúsìn Rẹ̀.
Verse 11
وَمِنَ ٱلنَّاسِ مَن يَعْبُدُ ٱللَّهَ عَلَىٰ حَرْفٍ ۖ فَإِنْ أَصَابَهُۥ خَيْرٌ ٱطْمَأَنَّ بِهِۦ ۖ وَإِنْ أَصَابَتْهُ فِتْنَةٌ ٱنقَلَبَ عَلَىٰ وَجْهِهِۦ خَسِرَ ٱلدُّنْيَا وَٱلْـَٔاخِرَةَ ۚ ذَٰلِكَ هُوَ ٱلْخُسْرَانُ ٱلْمُبِينُ
Transliteration wamina l-nāsi man yaʿbudu l-laha ʿalā ḥarfin fa-in aṣābahu khayrun iṭ'ma-anna bihi wa-in aṣābathu fit'natun inqalaba ʿalā wajhihi khasira l-dun'yā wal-ākhirata dhālika huwa l-khus'rānu l-mubīnu
Yoruba Ó tún wà nínú àwọn ènìyàn ẹni tó ń jọ́sìn fún Allāhu lórí ahọ́n. Tí rere bá ṣẹlẹ̀ sí i, ó máa fi ọkàn balẹ̀ (sínú ẹ̀sìn). Tí ìfòòró bá sì ṣẹlẹ̀ sí i, ó máa yíjú rẹ̀ padà kúrò nínú ẹ̀sìn. Ó ṣòfò láyé àti lọ́run. Ìyẹn sì ni òfò pọ́nńbélé.
Verse 12
يَدْعُوا۟ مِن دُونِ ٱللَّهِ مَا لَا يَضُرُّهُۥ وَمَا لَا يَنفَعُهُۥ ۚ ذَٰلِكَ هُوَ ٱلضَّلَـٰلُ ٱلْبَعِيدُ
Transliteration yadʿū min dūni l-lahi mā lā yaḍurruhu wamā lā yanfaʿuhu dhālika huwa l-ḍalālu l-baʿīdu
Yoruba Ó ń pè lẹ́yìn Allāhu ohun tí kò lè kó ìnira bá a, tí kò sì lè ṣe é ní oore; ìyẹn ni ìṣìnà tó jìnnà (sí ìmọ̀nà).
Verse 13
يَدْعُوا۟ لَمَن ضَرُّهُۥٓ أَقْرَبُ مِن نَّفْعِهِۦ ۚ لَبِئْسَ ٱلْمَوْلَىٰ وَلَبِئْسَ ٱلْعَشِيرُ
Transliteration yadʿū laman ḍarruhu aqrabu min nafʿihi labi'sa l-mawlā walabi'sa l-ʿashīru
Yoruba Ó ń pe ohun tí ìnira rẹ̀ súnmọ́ ju àǹfààní rẹ̀ lọ. Dájúdájú (òrìṣà) burú ní aláfẹ̀yìntì, ó sì burú ní alásùn-únmọ́.
Verse 14
إِنَّ ٱللَّهَ يُدْخِلُ ٱلَّذِينَ ءَامَنُوا۟ وَعَمِلُوا۟ ٱلصَّـٰلِحَـٰتِ جَنَّـٰتٍ تَجْرِى مِن تَحْتِهَا ٱلْأَنْهَـٰرُ ۚ إِنَّ ٱللَّهَ يَفْعَلُ مَا يُرِيدُ
Transliteration inna l-laha yud'khilu alladhīna āmanū waʿamilū l-ṣāliḥāti jannātin tajrī min taḥtihā l-anhāru inna l-laha yafʿalu mā yurīdu
Yoruba Dájúdájú Allāhu yóò mú àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe àwọn iṣẹ́ rere wọ inú Ọgbà Ìdẹ̀ra tí àwọn odò ń ṣàn ní ìsàlẹ̀ rẹ̀. Dájúdájú Allāhu ń ṣe ohun tí Ó bá fẹ́.
Verse 15
مَن كَانَ يَظُنُّ أَن لَّن يَنصُرَهُ ٱللَّهُ فِى ٱلدُّنْيَا وَٱلْـَٔاخِرَةِ فَلْيَمْدُدْ بِسَبَبٍ إِلَى ٱلسَّمَآءِ ثُمَّ لْيَقْطَعْ فَلْيَنظُرْ هَلْ يُذْهِبَنَّ كَيْدُهُۥ مَا يَغِيظُ
Transliteration man kāna yaẓunnu an lan yanṣurahu l-lahu fī l-dun'yā wal-ākhirati falyamdud bisababin ilā l-samāi thumma l'yaqṭaʿ falyanẓur hal yudh'hibanna kayduhu mā yaghīẓu
Yoruba Ẹnikẹ́ni tí ó bá lérò pé Allāhu kò níí ran (Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -) lọ́wọ́ láyé àti lọ́run, kí ó na okùn sí sánmọ̀ (àjà ilé rẹ̀) lẹ́yìn náà kí ó gé e (ìyẹn ni pé, kí ó pokùn so). Kí ó wò ó nígbà náà bóyá ète rẹ̀ lè mú (àrànṣe) tó ń bínú sí kúrò (lọ́dọ̀ Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -).1
Verse 16
وَكَذَٰلِكَ أَنزَلْنَـٰهُ ءَايَـٰتٍۭ بَيِّنَـٰتٍ وَأَنَّ ٱللَّهَ يَهْدِى مَن يُرِيدُ
Transliteration wakadhālika anzalnāhu āyātin bayyinātin wa-anna l-laha yahdī man yurīdu
Yoruba Báyẹn ni A ṣe sọ̀ ọ́ kalẹ̀ ní àwọn āyah tó yanjú. Dájúdájú Allāhu ń tọ́ ẹni tí Ó bá fẹ́ sí ọ̀nà.
Verse 17
إِنَّ ٱلَّذِينَ ءَامَنُوا۟ وَٱلَّذِينَ هَادُوا۟ وَٱلصَّـٰبِـِٔينَ وَٱلنَّصَـٰرَىٰ وَٱلْمَجُوسَ وَٱلَّذِينَ أَشْرَكُوٓا۟ إِنَّ ٱللَّهَ يَفْصِلُ بَيْنَهُمْ يَوْمَ ٱلْقِيَـٰمَةِ ۚ إِنَّ ٱللَّهَ عَلَىٰ كُلِّ شَىْءٍ شَهِيدٌ
Transliteration inna alladhīna āmanū wa-alladhīna hādū wal-ṣābiīna wal-naṣārā wal-majūsa wa-alladhīna ashrakū inna l-laha yafṣilu baynahum yawma l-qiyāmati inna l-laha ʿalā kulli shayin shahīdun
Yoruba Dájúdájú àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo àti àwọn tó di yẹhudi àti àwọn sọ̄bi’ūn àti àwọn nasọ̄rọ̄ àti àwọn mọjūs àti àwọn tó ṣẹbọ, dájúdájú Allāhu yóò ṣèdájọ́ láààrin wọn ní Ọjọ́ Àjíǹde. Dájúdájú Allāhu ni Arínú-róde gbogbo n̄ǹkan.1
Verse 18
أَلَمْ تَرَ أَنَّ ٱللَّهَ يَسْجُدُ لَهُۥ مَن فِى ٱلسَّمَـٰوَٰتِ وَمَن فِى ٱلْأَرْضِ وَٱلشَّمْسُ وَٱلْقَمَرُ وَٱلنُّجُومُ وَٱلْجِبَالُ وَٱلشَّجَرُ وَٱلدَّوَآبُّ وَكَثِيرٌ مِّنَ ٱلنَّاسِ ۖ وَكَثِيرٌ حَقَّ عَلَيْهِ ٱلْعَذَابُ ۗ وَمَن يُهِنِ ٱللَّهُ فَمَا لَهُۥ مِن مُّكْرِمٍ ۚ إِنَّ ٱللَّهَ يَفْعَلُ مَا يَشَآءُ ۩
Transliteration alam tara anna l-laha yasjudu lahu man fī l-samāwāti waman fī l-arḍi wal-shamsu wal-qamaru wal-nujūmu wal-jibālu wal-shajaru wal-dawābu wakathīrun mina l-nāsi wakathīrun ḥaqqa ʿalayhi l-ʿadhābu waman yuhini l-lahu famā lahu min muk'rimin inna l-laha yafʿalu mā yashāu
Yoruba Ṣé o ò wòye pé dájúdájú Allāhu ni àwọn tó ń bẹ nínú àwọn sánmọ̀ àti àwọn tó ń bẹ lórí ilẹ̀, àti òòrùn, òṣùpá, àwọn ìràwọ̀, àwọn àpáta, àwọn igi, àwọn n̄ǹkan ẹlẹ́mìí àti ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ nínú àwọn ènìyàn ń forí kanlẹ̀ fún? Ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ sì ni ìyà ti kò lé lórí. Ẹnikẹ́ni tí Allāhu bá fi àbùkù kàn, kò sí ẹnì kan tí ó máa ṣe àpọ́nlé rẹ̀. Dájúdájú Allāhu ń ṣe ohun tí Ó bá fẹ́.1
Verse 19
۞ هَـٰذَانِ خَصْمَانِ ٱخْتَصَمُوا۟ فِى رَبِّهِمْ ۖ فَٱلَّذِينَ كَفَرُوا۟ قُطِّعَتْ لَهُمْ ثِيَابٌ مِّن نَّارٍ يُصَبُّ مِن فَوْقِ رُءُوسِهِمُ ٱلْحَمِيمُ
Transliteration hādhāni khaṣmāni ikh'taṣamū fī rabbihim fa-alladhīna kafarū quṭṭiʿat lahum thiyābun min nārin yuṣabbu min fawqi ruūsihimu l-ḥamīmu
Yoruba Àwọn oníjà méjì (kan) nìyí, wọ́n ń takò ara wọn nípa Olúwa wọn. Nítorí náà, àwọn tó ṣàì gbàgbọ́, wọ́n máa gé aṣọ Iná fún wọn, wọ́n yó sì máa da omi tó gbóná gan-an lé wọn lórí láti òkè orí wọn.
Verse 20
يُصْهَرُ بِهِۦ مَا فِى بُطُونِهِمْ وَٱلْجُلُودُ
Transliteration yuṣ'haru bihi mā fī buṭūnihim wal-julūdu
Yoruba Wọ́n máa fi yọ́ ohun tí ń bẹ nínú ikùn wọn àti awọ ara wọn.
Verse 21
وَلَهُم مَّقَـٰمِعُ مِنْ حَدِيدٍ
Transliteration walahum maqāmiʿu min ḥadīdin
Yoruba Àwọn òdùrọ irin (ìyà) sì wà fún wọn pẹ̀lú.
Verse 22
كُلَّمَآ أَرَادُوٓا۟ أَن يَخْرُجُوا۟ مِنْهَا مِنْ غَمٍّ أُعِيدُوا۟ فِيهَا وَذُوقُوا۟ عَذَابَ ٱلْحَرِيقِ
Transliteration kullamā arādū an yakhrujū min'hā min ghammin uʿīdū fīhā wadhūqū ʿadhāba l-ḥarīqi
Yoruba Ìgbàkígbà tí wọ́n bá fẹ́ jáde kúrò nínú rẹ̀ látara ìbànújẹ́, wọ́n á dá wọn padà sínú rẹ̀. (A óò sọ pé): “Ẹ tọ́ ìyà Iná jónijóni wò.”
Verse 23
إِنَّ ٱللَّهَ يُدْخِلُ ٱلَّذِينَ ءَامَنُوا۟ وَعَمِلُوا۟ ٱلصَّـٰلِحَـٰتِ جَنَّـٰتٍ تَجْرِى مِن تَحْتِهَا ٱلْأَنْهَـٰرُ يُحَلَّوْنَ فِيهَا مِنْ أَسَاوِرَ مِن ذَهَبٍ وَلُؤْلُؤًا ۖ وَلِبَاسُهُمْ فِيهَا حَرِيرٌ
Transliteration inna l-laha yud'khilu alladhīna āmanū waʿamilū l-ṣāliḥāti jannātin tajrī min taḥtihā l-anhāru yuḥallawna fīhā min asāwira min dhahabin walu'lu-an walibāsuhum fīhā ḥarīrun
Yoruba Dájúdájú Allāhu yóò fi àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe àwọn iṣẹ́ rere wọ inú àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra, tí àwọn odò ń ṣàn ní ìsàlẹ̀ rẹ̀. A óò ṣe wọ́n ní ọ̀ṣọ́ nínú rẹ̀ pẹ̀lú ẹ̀gbà wúrà àti àlúùlúù. Aṣọ àlàárì sì ni aṣọ wọn nínú rẹ̀.
Verse 24
وَهُدُوٓا۟ إِلَى ٱلطَّيِّبِ مِنَ ٱلْقَوْلِ وَهُدُوٓا۟ إِلَىٰ صِرَٰطِ ٱلْحَمِيدِ
Transliteration wahudū ilā l-ṭayibi mina l-qawli wahudū ilā ṣirāṭi l-ḥamīdi
Yoruba A fún wọn ní ìmọ̀nà síbi ohun tó dára nínú ọ̀rọ̀.A sì tọ́ wọn sí ọ̀nà Ẹlẹ́yìn.
Verse 25
إِنَّ ٱلَّذِينَ كَفَرُوا۟ وَيَصُدُّونَ عَن سَبِيلِ ٱللَّهِ وَٱلْمَسْجِدِ ٱلْحَرَامِ ٱلَّذِى جَعَلْنَـٰهُ لِلنَّاسِ سَوَآءً ٱلْعَـٰكِفُ فِيهِ وَٱلْبَادِ ۚ وَمَن يُرِدْ فِيهِ بِإِلْحَادٍۭ بِظُلْمٍ نُّذِقْهُ مِنْ عَذَابٍ أَلِيمٍ
Transliteration inna alladhīna kafarū wayaṣuddūna ʿan sabīli l-lahi wal-masjidi l-ḥarāmi alladhī jaʿalnāhu lilnnāsi sawāan l-ʿākifu fīhi wal-bādi waman yurid fīhi bi-il'ḥādin biẓul'min nudhiq'hu min ʿadhābin alīmin
Yoruba Dájúdájú àwọn tó ṣàì gbàgbọ́, tí wọ́n ń ṣẹ́rí àwọn ènìyàn kúrò lójú ọ̀nà (ẹ̀sìn) Allāhu àti Mọ́sálásí Haram, èyí tí A ṣe ní dọ́gbadọ́gba fún àwọn ènìyàn, olùgbé-inú rẹ̀ àti àlejò (fún ìjọ́sìn ṣíṣe), ẹnikẹ́ni tí ó bá ní èrò láti ṣe ìyípadà kan níbẹ̀ pẹ̀lú àbòsí, A máa mú un tọ́ ìyà ẹlẹ́ta-eléro wò.
Verse 26
وَإِذْ بَوَّأْنَا لِإِبْرَٰهِيمَ مَكَانَ ٱلْبَيْتِ أَن لَّا تُشْرِكْ بِى شَيْـًٔا وَطَهِّرْ بَيْتِىَ لِلطَّآئِفِينَ وَٱلْقَآئِمِينَ وَٱلرُّكَّعِ ٱلسُّجُودِ
Transliteration wa-idh bawwanā li-ib'rāhīma makāna l-bayti an lā tush'rik bī shayan waṭahhir baytiya lilṭṭāifīna wal-qāimīna wal-rukaʿi l-sujūdi
Yoruba (Ẹ rántí) nígbà tí A ṣàfi hàn àyè ilé náà fún (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm (A sì pa á láṣẹ) pé o ò gbọdọ̀ sọ kiní kan di akẹgbẹ́ fún Mi. Àti pé kí o ṣe ilé Mi ní mímọ́ fún àwọn olùyípo rẹ̀, olùkírun, olùdáwọ́tẹ-orúnkún àti olùforíkanlẹ̀.
Verse 27
وَأَذِّن فِى ٱلنَّاسِ بِٱلْحَجِّ يَأْتُوكَ رِجَالًا وَعَلَىٰ كُلِّ ضَامِرٍ يَأْتِينَ مِن كُلِّ فَجٍّ عَمِيقٍ
Transliteration wa-adhin fī l-nāsi bil-ḥaji yatūka rijālan waʿalā kulli ḍāmirin yatīna min kulli fajjin ʿamīqin
Yoruba Kí o sì pe ìpè fún àwọn ènìyàn fún iṣẹ́ Hajj. Wọn yóò wá bá ọ pẹ̀lú ìrìn ẹsẹ̀ àti lórí gbogbo n̄ǹkan ìgùn, wọn yóò máa wá láti àwọn ọ̀nà jíjìn
Verse 28
لِّيَشْهَدُوا۟ مَنَـٰفِعَ لَهُمْ وَيَذْكُرُوا۟ ٱسْمَ ٱللَّهِ فِىٓ أَيَّامٍ مَّعْلُومَـٰتٍ عَلَىٰ مَا رَزَقَهُم مِّنۢ بَهِيمَةِ ٱلْأَنْعَـٰمِ ۖ فَكُلُوا۟ مِنْهَا وَأَطْعِمُوا۟ ٱلْبَآئِسَ ٱلْفَقِيرَ
Transliteration liyashhadū manāfiʿa lahum wayadhkurū is'ma l-lahi fī ayyāmin maʿlūmātin ʿalā mā razaqahum min bahīmati l-anʿāmi fakulū min'hā wa-aṭʿimū l-bāisa l-faqīra
Yoruba nítorí kí wọ́n lè rí àwọn àǹfààní tó ń bẹ fún wọn àti nítorí kí wọ́n lè ṣèrántí orúkọ Allāhu fún àwọn ọjọ́ tí wọ́n ti mọ̀lórí n̄ǹkan tí Allāhu pa lésè fún wọn nínú àwọn ẹran-ọ̀sìn. Nítorí náà, ẹ jẹ nínú rẹ̀, kí ẹ sì fi bọ́ aláìlera, tálíkà.
Verse 29
ثُمَّ لْيَقْضُوا۟ تَفَثَهُمْ وَلْيُوفُوا۟ نُذُورَهُمْ وَلْيَطَّوَّفُوا۟ بِٱلْبَيْتِ ٱلْعَتِيقِ
Transliteration thumma l'yaqḍū tafathahum walyūfū nudhūrahum walyaṭṭawwafū bil-bayti l-ʿatīqi
Yoruba Lẹ́yìn náà, kí wọ́n yanjú ìdọ̀tí ara wọn fún ìparí iṣẹ́ Hajj wọn, kí wọ́n mú àwọn ẹ̀jẹ́ wọn ṣẹ, kí wọ́n sì yípo Ilé Láéláé náà.
Verse 30
ذَٰلِكَ وَمَن يُعَظِّمْ حُرُمَـٰتِ ٱللَّهِ فَهُوَ خَيْرٌ لَّهُۥ عِندَ رَبِّهِۦ ۗ وَأُحِلَّتْ لَكُمُ ٱلْأَنْعَـٰمُ إِلَّا مَا يُتْلَىٰ عَلَيْكُمْ ۖ فَٱجْتَنِبُوا۟ ٱلرِّجْسَ مِنَ ٱلْأَوْثَـٰنِ وَٱجْتَنِبُوا۟ قَوْلَ ٱلزُّورِ
Transliteration dhālika waman yuʿaẓẓim ḥurumāti l-lahi fahuwa khayrun lahu ʿinda rabbihi wa-uḥillat lakumu l-anʿāmu illā mā yut'lā ʿalaykum fa-ij'tanibū l-rij'sa mina l-awthāni wa-ij'tanibū qawla l-zūri
Yoruba Ìyẹn (nìyẹn). Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì pàtàkì àwọn n̄ǹkan tí Allāhu bu ọ̀wọ̀ fún, òhun ló lóore jùlọ fún un lọ́dọ̀ Olúwa rẹ̀. Wọ́n sì ṣe àwọn ẹran-ọ̀sìn ní ẹ̀tọ́ fún yín àyàfi àwọn tí wọ́n ń kà (ní èèwọ̀) fún yín. Nítorí náà, ẹ jìnnà sí ẹ̀gbin òrìṣà. Kí ẹ sì jìnnà sí ọ̀rọ̀ irọ́.
Verse 31
حُنَفَآءَ لِلَّهِ غَيْرَ مُشْرِكِينَ بِهِۦ ۚ وَمَن يُشْرِكْ بِٱللَّهِ فَكَأَنَّمَا خَرَّ مِنَ ٱلسَّمَآءِ فَتَخْطَفُهُ ٱلطَّيْرُ أَوْ تَهْوِى بِهِ ٱلرِّيحُ فِى مَكَانٍ سَحِيقٍ
Transliteration ḥunafāa lillahi ghayra mush'rikīna bihi waman yush'rik bil-lahi faka-annamā kharra mina l-samāi fatakhṭafuhu l-ṭayru aw tahwī bihi l-rīḥu fī makānin saḥīqin
Yoruba (Ẹ jẹ́) olùdúró-déédé-nínú-ẹ̀sìn fún Allāhu, ẹ má ṣe jẹ́ ẹni tí yóò máa ṣẹbọ sí I. Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣẹbọ sí Allāhu, ó dà bí ẹni tó jábọ́ láti ojú sánmọ̀, tí ẹyẹ sì gbé e lọ tàbí (tí) atẹ́gùn jù ú sínú àyè tó jìnnà.1
Verse 32
ذَٰلِكَ وَمَن يُعَظِّمْ شَعَـٰٓئِرَ ٱللَّهِ فَإِنَّهَا مِن تَقْوَى ٱلْقُلُوبِ
Transliteration dhālika waman yuʿaẓẓim shaʿāira l-lahi fa-innahā min taqwā l-qulūbi
Yoruba Ìyẹn (nìyẹn). Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì pàtàkì àwọn n̄ǹkan tí Allāhu fi ṣe àríṣàmì fún ẹ̀sìn ’Islām, dájúdájú ó wà lára níní ìbẹ̀rù Allāhu nínú ọkàn.
Verse 33
لَكُمْ فِيهَا مَنَـٰفِعُ إِلَىٰٓ أَجَلٍ مُّسَمًّى ثُمَّ مَحِلُّهَآ إِلَى ٱلْبَيْتِ ٱلْعَتِيقِ
Transliteration lakum fīhā manāfiʿu ilā ajalin musamman thumma maḥilluhā ilā l-bayti l-ʿatīqi
Yoruba Àwọn àǹfààní wà fún yín lára àwọn ẹran-ọ̀sìn títí di gbèdéke àkókò kan. Lẹ́yìn náà, Ilé Láéláé náà ni ibùpa àwọn ẹran náà.
Verse 34
وَلِكُلِّ أُمَّةٍ جَعَلْنَا مَنسَكًا لِّيَذْكُرُوا۟ ٱسْمَ ٱللَّهِ عَلَىٰ مَا رَزَقَهُم مِّنۢ بَهِيمَةِ ٱلْأَنْعَـٰمِ ۗ فَإِلَـٰهُكُمْ إِلَـٰهٌ وَٰحِدٌ فَلَهُۥٓ أَسْلِمُوا۟ ۗ وَبَشِّرِ ٱلْمُخْبِتِينَ
Transliteration walikulli ummatin jaʿalnā mansakan liyadhkurū is'ma l-lahi ʿalā mā razaqahum min bahīmati l-anʿāmi fa-ilāhukum ilāhun wāḥidun falahu aslimū wabashiri l-mukh'bitīna
Yoruba Ìkọ̀ọ̀kan ìjọ (mùsùlùmí tó ṣíwájú) ni A yan ẹran pípa fún nítorí kí wọ́n lè dárúkọ Allāhu lórí ohun tí Ó pèsè fún wọn nínú àwọn ẹran-ọ̀sìn. Nítorí náà, Ọlọ́hun yín tí ẹ gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo, Ọlọ́hun Ọ̀kan ṣoṣo ni. Òun ni kí ẹ jẹ́ mùsùlùmí fún. Kí o sì fún àwọn ọlọ́kàn ìrẹ̀lẹ̀, àwọn olùfọkànbalẹ̀ sọ́dọ̀ Allāhu ní ìró ìdùnnú.
Verse 35
ٱلَّذِينَ إِذَا ذُكِرَ ٱللَّهُ وَجِلَتْ قُلُوبُهُمْ وَٱلصَّـٰبِرِينَ عَلَىٰ مَآ أَصَابَهُمْ وَٱلْمُقِيمِى ٱلصَّلَوٰةِ وَمِمَّا رَزَقْنَـٰهُمْ يُنفِقُونَ
Transliteration alladhīna idhā dhukira l-lahu wajilat qulūbuhum wal-ṣābirīna ʿalā mā aṣābahum wal-muqīmī l-ṣalati wamimmā razaqnāhum yunfiqūna
Yoruba (Àwọn ni) àwọn tí ó jẹ́ pé tí A bá dárúkọ Allāhu (fún wọn), ọkàn wọn máa gbọ̀n rìrì. (Wọ́n jẹ́) onísùúrù lórí ohun tí ó bá ṣẹlẹ̀ sí wọn. (Wọ́n jẹ́) olùkírun. Wọ́n sì ń ná nínú ohun tí A pa lésè fùn wọn.
Verse 36
وَٱلْبُدْنَ جَعَلْنَـٰهَا لَكُم مِّن شَعَـٰٓئِرِ ٱللَّهِ لَكُمْ فِيهَا خَيْرٌ ۖ فَٱذْكُرُوا۟ ٱسْمَ ٱللَّهِ عَلَيْهَا صَوَآفَّ ۖ فَإِذَا وَجَبَتْ جُنُوبُهَا فَكُلُوا۟ مِنْهَا وَأَطْعِمُوا۟ ٱلْقَانِعَ وَٱلْمُعْتَرَّ ۚ كَذَٰلِكَ سَخَّرْنَـٰهَا لَكُمْ لَعَلَّكُمْ تَشْكُرُونَ
Transliteration wal-bud'na jaʿalnāhā lakum min shaʿāiri l-lahi lakum fīhā khayrun fa-udh'kurū is'ma l-lahi ʿalayhā ṣawāffa fa-idhā wajabat junūbuhā fakulū min'hā wa-aṭʿimū l-qāniʿa wal-muʿ'tara kadhālika sakharnāhā lakum laʿallakum tashkurūna
Yoruba Àwọn ràkúnmí, A ṣe wọ́n nínú àwọn n̄ǹkan àríṣàmì fún ẹ̀sìn Allāhu fún yín. Oore wà lára wọn fún yín. Nítorí náà, ẹ dárúkọ Allāhu lé wọn lórí (kí ẹ sì gún wọn) ní ìdúró. Nígbà tí wọ́n bá fi ẹ̀gbẹ́ lélẹ̀, ẹ jẹ nínú rẹ̀. Ẹ fi bọ́ ẹni tó ní ìtẹ́lọ́rùn àti atọrọjẹ. Báyẹn ni A ṣe rọ̀ wọ́n fún yín nítorí kí ẹ lè dúpẹ́ (fún Un).
Verse 37
لَن يَنَالَ ٱللَّهَ لُحُومُهَا وَلَا دِمَآؤُهَا وَلَـٰكِن يَنَالُهُ ٱلتَّقْوَىٰ مِنكُمْ ۚ كَذَٰلِكَ سَخَّرَهَا لَكُمْ لِتُكَبِّرُوا۟ ٱللَّهَ عَلَىٰ مَا هَدَىٰكُمْ ۗ وَبَشِّرِ ٱلْمُحْسِنِينَ
Transliteration lan yanāla l-laha luḥūmuhā walā dimāuhā walākin yanāluhu l-taqwā minkum kadhālika sakharahā lakum litukabbirū l-laha ʿalā mā hadākum wabashiri l-muḥ'sinīna
Yoruba Ẹran (tí ẹ pa) àti ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ kò níí dé ọ̀dọ̀ Allāhu. Ṣùgbọ́n ìbẹ̀rù Allāhu láti ọ̀dọ̀ yín ló máa dé ọ̀dọ̀ Rẹ̀. Báyẹn ni (Allāhu) ṣe rọ̀ wọ́n fún yín nítorí kí ẹ lè ṣe ìgbétóbi fún Allāhu nípa bí Ó ṣe fi ọ̀nà mọ̀ yín. Kí o sì fún àwọn olùṣe-rere ní ìró ìdùnnú.
Verse 38
۞ إِنَّ ٱللَّهَ يُدَٰفِعُ عَنِ ٱلَّذِينَ ءَامَنُوٓا۟ ۗ إِنَّ ٱللَّهَ لَا يُحِبُّ كُلَّ خَوَّانٍ كَفُورٍ
Transliteration inna l-laha yudāfiʿu ʿani alladhīna āmanū inna l-laha lā yuḥibbu kulla khawwānin kafūrin
Yoruba Dájúdájú Allāhu ń ti aburú kúrò fún àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo. Dájúdájú Allāhu kò nífẹ̀ẹ́ gbogbo àwọn oníjàǹbá, aláìgbàgbọ́.
Verse 39
أُذِنَ لِلَّذِينَ يُقَـٰتَلُونَ بِأَنَّهُمْ ظُلِمُوا۟ ۚ وَإِنَّ ٱللَّهَ عَلَىٰ نَصْرِهِمْ لَقَدِيرٌ
Transliteration udhina lilladhīna yuqātalūna bi-annahum ẓulimū wa-inna l-laha ʿalā naṣrihim laqadīrun
Yoruba A yọ̀ǹda (ogun ẹ̀sìn jíjà) fún àwọn (mùsùlùmí) tí (àwọn kèfèrí) ń gbógun tì nítorí pé (àwọn kèfèrí) ti ṣe àbòsí sí wọn. Dájúdájú Allāhu ni Alágbára lórí àrànṣe wọn.
Verse 40
ٱلَّذِينَ أُخْرِجُوا۟ مِن دِيَـٰرِهِم بِغَيْرِ حَقٍّ إِلَّآ أَن يَقُولُوا۟ رَبُّنَا ٱللَّهُ ۗ وَلَوْلَا دَفْعُ ٱللَّهِ ٱلنَّاسَ بَعْضَهُم بِبَعْضٍ لَّهُدِّمَتْ صَوَٰمِعُ وَبِيَعٌ وَصَلَوَٰتٌ وَمَسَـٰجِدُ يُذْكَرُ فِيهَا ٱسْمُ ٱللَّهِ كَثِيرًا ۗ وَلَيَنصُرَنَّ ٱللَّهُ مَن يَنصُرُهُۥٓ ۗ إِنَّ ٱللَّهَ لَقَوِىٌّ عَزِيزٌ
Transliteration alladhīna ukh'rijū min diyārihim bighayri ḥaqqin illā an yaqūlū rabbunā l-lahu walawlā dafʿu l-lahi l-nāsa baʿḍahum bibaʿḍin lahuddimat ṣawāmiʿu wabiyaʿun waṣalawātun wamasājidu yudh'karu fīhā us'mu l-lahi kathīran walayanṣuranna l-lahu man yanṣuruhu inna l-laha laqawiyyun ʿazīzun
Yoruba (Àwọn ni) àwọn tí wọ́n lé jáde kúrò nínú ìlú wọn ní ọ̀nà àìtọ́ àfi (nítorí pé) wọ́n ń sọ pé: “Allāhu ni Olúwa wa.” Tí kò bá jẹ́ pé Allāhu ń dènà (aburú) fún àwọn ènìyàn ni, tí Ó ń fi apá kan wọn dènà (aburú) fún apá kan, wọn ìbá ti wó ilé ìsìn àwọn fadá, ṣọ́ọ̀ṣì, sínágọ́gù àti àwọn mọ́sálásí tí wọ́n ti ń dárúkọ Allāhu ní ọ̀pọ̀lọ́pọ̀.Dájúdájú Allāhu yóò ṣe àrànṣe fún ẹnikẹ́ni tó ń ran (ẹ̀sìn ’Islām) Rẹ̀ lọ́wọ́. Dájúdájú Allāhu mà ni Alágbára, Olùborí.2
Verse 41
ٱلَّذِينَ إِن مَّكَّنَّـٰهُمْ فِى ٱلْأَرْضِ أَقَامُوا۟ ٱلصَّلَوٰةَ وَءَاتَوُا۟ ٱلزَّكَوٰةَ وَأَمَرُوا۟ بِٱلْمَعْرُوفِ وَنَهَوْا۟ عَنِ ٱلْمُنكَرِ ۗ وَلِلَّهِ عَـٰقِبَةُ ٱلْأُمُورِ
Transliteration alladhīna in makkannāhum fī l-arḍi aqāmū l-ṣalata waātawū l-zakata wa-amarū bil-maʿrūfi wanahaw ʿani l-munkari walillahi ʿāqibatu l-umūri
Yoruba (Àwọn náà ni) àwọn tí ó jẹ́ pé tí A bá fún wọn ní ipò lórí ilẹ̀, wọn yóò kírun, wọn yóò yọ Zakāh, wọn yóò pàṣẹ ohun rere, wọn yó sì kọ ohun burúkú. Ti Allāhu sì ni ìkángun àwọn ọ̀rọ̀ ẹ̀dá.
Verse 42
وَإِن يُكَذِّبُوكَ فَقَدْ كَذَّبَتْ قَبْلَهُمْ قَوْمُ نُوحٍ وَعَادٌ وَثَمُودُ
Transliteration wa-in yukadhibūka faqad kadhabat qablahum qawmu nūḥin waʿādun wathamūdu
Yoruba Tí wọ́n bá pè ọ́ ní òpùrọ́, àwọn ìjọ Nūh, ìjọ ‘Ād àti ìjọ Thamūd kúkú ti pe àwọn Òjíṣẹ́ wọn ní òpùrọ́ ṣíwájú wọn.
Verse 43
وَقَوْمُ إِبْرَٰهِيمَ وَقَوْمُ لُوطٍ
Transliteration waqawmu ib'rāhīma waqawmu lūṭin
Yoruba Àti pé ìjọ ’Ibrọhīm àti ìjọ (Ànábì) Lūt,
Verse 44
وَأَصْحَـٰبُ مَدْيَنَ ۖ وَكُذِّبَ مُوسَىٰ فَأَمْلَيْتُ لِلْكَـٰفِرِينَ ثُمَّ أَخَذْتُهُمْ ۖ فَكَيْفَ كَانَ نَكِيرِ
Transliteration wa-aṣḥābu madyana wakudhiba mūsā fa-amlaytu lil'kāfirīna thumma akhadhtuhum fakayfa kāna nakīri
Yoruba àti àwọn ará ìlú Mọdyan (àwọn náà ṣe bẹ́ẹ̀). Wọ́n tún pe (Ànábì) Mūsā ní òpùrọ́. Mo sì lọ́ àwọn aláìgbàgbọ́ lára. Lẹ́yìn náà, Mo gbá wọn mú. Báwo sì ni bí Mo ṣe (fi ìyà) kọ (aburú fún wọn) ti rí!
Verse 45
فَكَأَيِّن مِّن قَرْيَةٍ أَهْلَكْنَـٰهَا وَهِىَ ظَالِمَةٌ فَهِىَ خَاوِيَةٌ عَلَىٰ عُرُوشِهَا وَبِئْرٍ مُّعَطَّلَةٍ وَقَصْرٍ مَّشِيدٍ
Transliteration faka-ayyin min qaryatin ahlaknāhā wahiya ẓālimatun fahiya khāwiyatun ʿalā ʿurūshihā wabi'rin muʿaṭṭalatin waqaṣrin mashīdin
Yoruba Nítorí náà, mélòó mélòó nínú ìlú tí A ti parẹ́ nígbà tí wọ́n jẹ́ alábòsí; àwọn ilé wọn dàwó lulẹ̀ pẹ̀lú òrùlé rẹ̀. (Mélòó mélòó nínú) kànǹga tí wọ́n ti patì (nípasẹ̀ ìparun) àti ilé pẹ̀tẹ́ẹ̀sì oníbíríkì (tó ti dahoro)!
Verse 46
أَفَلَمْ يَسِيرُوا۟ فِى ٱلْأَرْضِ فَتَكُونَ لَهُمْ قُلُوبٌ يَعْقِلُونَ بِهَآ أَوْ ءَاذَانٌ يَسْمَعُونَ بِهَا ۖ فَإِنَّهَا لَا تَعْمَى ٱلْأَبْصَـٰرُ وَلَـٰكِن تَعْمَى ٱلْقُلُوبُ ٱلَّتِى فِى ٱلصُّدُورِ
Transliteration afalam yasīrū fī l-arḍi fatakūna lahum qulūbun yaʿqilūna bihā aw ādhānun yasmaʿūna bihā fa-innahā lā taʿmā l-abṣāru walākin taʿmā l-qulūbu allatī fī l-ṣudūri
Yoruba Ṣé wọn kò rìn kiri lórí ilẹ̀ kí wọ́n sì ní àwọn ọkàn tí wọ́n máa fi ṣe làákàyè tàbí àwọn etí tí wọn máa fi gbọ́rọ̀? Dájúdájú àwọn ojú kò fọ́, ṣùgbọ́n àwọn ọkàn tó wà nínú igbá-àyà ló ń fọ́.
Verse 47
وَيَسْتَعْجِلُونَكَ بِٱلْعَذَابِ وَلَن يُخْلِفَ ٱللَّهُ وَعْدَهُۥ ۚ وَإِنَّ يَوْمًا عِندَ رَبِّكَ كَأَلْفِ سَنَةٍ مِّمَّا تَعُدُّونَ
Transliteration wayastaʿjilūnaka bil-ʿadhābi walan yukh'lifa l-lahu waʿdahu wa-inna yawman ʿinda rabbika ka-alfi sanatin mimmā taʿuddūna
Yoruba Wọ́n sì ń kán ọ lójú fún ìyà náà. Allāhu kò sì níí yapa àdéhùn Rẹ̀. Dájúdájú ọjọ́ kan lọ́dọ̀ Olúwa rẹ dà bí ẹgbẹ̀rún ọdún nínú ohun tí ẹ̀ ń kà (ní òǹkà).1
Verse 48
وَكَأَيِّن مِّن قَرْيَةٍ أَمْلَيْتُ لَهَا وَهِىَ ظَالِمَةٌ ثُمَّ أَخَذْتُهَا وَإِلَىَّ ٱلْمَصِيرُ
Transliteration waka-ayyin min qaryatin amlaytu lahā wahiya ẓālimatun thumma akhadhtuhā wa-ilayya l-maṣīru
Yoruba Mélòó mélòó nínú ìlú tí Mo lọ́ lára, tí wọ́n jẹ́ alábòsí. Lẹ́yìn náà, Mo gbá wọn mú. Ọ̀dọ̀ Mi sì ni àbọ̀ ẹ̀dá.
Verse 49
قُلْ يَـٰٓأَيُّهَا ٱلنَّاسُ إِنَّمَآ أَنَا۠ لَكُمْ نَذِيرٌ مُّبِينٌ
Transliteration qul yāayyuhā l-nāsu innamā anā lakum nadhīrun mubīnun
Yoruba Sọ pé: “Ẹ̀yin ènìyàn, èmi mà ni olùkìlọ̀ pọ́nńbélé fún yín.”
Verse 50
فَٱلَّذِينَ ءَامَنُوا۟ وَعَمِلُوا۟ ٱلصَّـٰلِحَـٰتِ لَهُم مَّغْفِرَةٌ وَرِزْقٌ كَرِيمٌ
Transliteration fa-alladhīna āmanū waʿamilū l-ṣāliḥāti lahum maghfiratun wariz'qun karīmun
Yoruba Nítorí náà, àwọn tó bá gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe iṣẹ́ rere, àforíjìn àti arísìkí alápọ̀n-ọ́nlé ń bẹ fún wọn.
Verse 51
وَٱلَّذِينَ سَعَوْا۟ فِىٓ ءَايَـٰتِنَا مُعَـٰجِزِينَ أُو۟لَـٰٓئِكَ أَصْحَـٰبُ ٱلْجَحِيمِ
Transliteration wa-alladhīna saʿaw fī āyātinā muʿājizīna ulāika aṣḥābu l-jaḥīmi
Yoruba Àwọn tó ṣe iṣẹ́ (burúkú) nípa àwọn āyah Wa, tí wọ́n ń dá àwọn ènìyàn ní agara (láti tẹ̀lé àwọn āyah Wa, tí wọ́n sì lérò pé àwọn máa mórí bọ́ lọ́dọ̀ Allāhu); àwọn wọ̀nyẹn ni èrò inú iná Jẹhīm.
Verse 52
وَمَآ أَرْسَلْنَا مِن قَبْلِكَ مِن رَّسُولٍ وَلَا نَبِىٍّ إِلَّآ إِذَا تَمَنَّىٰٓ أَلْقَى ٱلشَّيْطَـٰنُ فِىٓ أُمْنِيَّتِهِۦ فَيَنسَخُ ٱللَّهُ مَا يُلْقِى ٱلشَّيْطَـٰنُ ثُمَّ يُحْكِمُ ٱللَّهُ ءَايَـٰتِهِۦ ۗ وَٱللَّهُ عَلِيمٌ حَكِيمٌ
Transliteration wamā arsalnā min qablika min rasūlin walā nabiyyin illā idhā tamannā alqā l-shayṭānu fī um'niyyatihi fayansakhu l-lahu mā yul'qī l-shayṭānu thumma yuḥ'kimu l-lahu āyātihi wal-lahu ʿalīmun ḥakīmun
Yoruba A kò rán Òjíṣẹ́ kan tàbí Ànábì kan níṣẹ́ ṣíwájú rẹ àfi kí ó jẹ́ pé nígbà tí ó bá sọ̀rọ̀, Èṣù máa ju (n̄ǹkan) sínú ọ̀rọ̀ rẹ̀. Nítorí náà, Allāhu yóò pa ohun tí Èṣù ń jù sínú rẹ̀ rẹ́. Lẹ́yìn náà, Ó máa fi òdodo àwọn āyah Rẹ̀ rinlẹ̀. Allāhu sì ni Onímọ̀, Ọlọ́gbọ́n. 1
Verse 53
لِّيَجْعَلَ مَا يُلْقِى ٱلشَّيْطَـٰنُ فِتْنَةً لِّلَّذِينَ فِى قُلُوبِهِم مَّرَضٌ وَٱلْقَاسِيَةِ قُلُوبُهُمْ ۗ وَإِنَّ ٱلظَّـٰلِمِينَ لَفِى شِقَاقٍۭ بَعِيدٍ
Transliteration liyajʿala mā yul'qī l-shayṭānu fit'natan lilladhīna fī qulūbihim maraḍun wal-qāsiyati qulūbuhum wa-inna l-ẓālimīna lafī shiqāqin baʿīdin
Yoruba (Èyí ń ṣẹlẹ̀) nítorí kí (Allāhu) lè fi ohun tí Èṣù ń jù (sínú rẹ̀) ṣe àdánwò fún àwọn tí àìsàn ń bẹ nínú ọkàn wọn àti àwọn tí ọkàn wọn le. Dájúdájú àwọn alábòsí sì wà nínú ìyapa tó jìnnà (sí òdodo).
Verse 54
وَلِيَعْلَمَ ٱلَّذِينَ أُوتُوا۟ ٱلْعِلْمَ أَنَّهُ ٱلْحَقُّ مِن رَّبِّكَ فَيُؤْمِنُوا۟ بِهِۦ فَتُخْبِتَ لَهُۥ قُلُوبُهُمْ ۗ وَإِنَّ ٱللَّهَ لَهَادِ ٱلَّذِينَ ءَامَنُوٓا۟ إِلَىٰ صِرَٰطٍ مُّسْتَقِيمٍ
Transliteration waliyaʿlama alladhīna ūtū l-ʿil'ma annahu l-ḥaqu min rabbika fayu'minū bihi fatukh'bita lahu qulūbuhum wa-inna l-laha lahādi alladhīna āmanū ilā ṣirāṭin mus'taqīmin
Yoruba (Èyí ń ṣẹlẹ̀) nítorí kí àwọn tí A fún ní ìmọ̀ lè mọ̀ pé dájúdájú al-Ƙur’ān jẹ́ òdodo láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ. Nítorí náà, wọn yó sì gbàgbọ́ nínú rẹ̀, ọkàn wọn yó sì balẹ̀ sí i. Dájúdájú Allāhu l’Ó ń fi ẹsẹ̀ àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo rinlẹ̀ sójú ọ̀nà tààrà (’Islām).
Verse 55
وَلَا يَزَالُ ٱلَّذِينَ كَفَرُوا۟ فِى مِرْيَةٍ مِّنْهُ حَتَّىٰ تَأْتِيَهُمُ ٱلسَّاعَةُ بَغْتَةً أَوْ يَأْتِيَهُمْ عَذَابُ يَوْمٍ عَقِيمٍ
Transliteration walā yazālu alladhīna kafarū fī mir'yatin min'hu ḥattā tatiyahumu l-sāʿatu baghtatan aw yatiyahum ʿadhābu yawmin ʿaqīmin
Yoruba Àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ kò sì níí yé wà nínú iyèméjì nípa rẹ̀ títí Àkókò náà yóò fi dé bá wọn ní òjijì tàbí (títí) ìyà ọjọ́ ìparun yóò fi dé bá wọn.
Verse 56
ٱلْمُلْكُ يَوْمَئِذٍ لِّلَّهِ يَحْكُمُ بَيْنَهُمْ ۚ فَٱلَّذِينَ ءَامَنُوا۟ وَعَمِلُوا۟ ٱلصَّـٰلِحَـٰتِ فِى جَنَّـٰتِ ٱلنَّعِيمِ
Transliteration al-mul'ku yawma-idhin lillahi yaḥkumu baynahum fa-alladhīna āmanū waʿamilū l-ṣāliḥāti fī jannāti l-naʿīmi
Yoruba Gbogbo ìjọba ọjọ́ yẹn ń jẹ́ ti Allāhu tí Ó máa ṣèdájọ́ láààrin wọn. Nítorí náà, àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe àwọn iṣẹ́ rere, (wọn yóò wà) nínú àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra.
Verse 57
وَٱلَّذِينَ كَفَرُوا۟ وَكَذَّبُوا۟ بِـَٔايَـٰتِنَا فَأُو۟لَـٰٓئِكَ لَهُمْ عَذَابٌ مُّهِينٌ
Transliteration wa-alladhīna kafarū wakadhabū biāyātinā fa-ulāika lahum ʿadhābun muhīnun
Yoruba Àwọn tó sì ṣàì gbàgbọ́, tí wọ́n tún pe àwọn āyah Wa ní irọ́; àwọn wọ̀nyẹn ni ìyà tí í yẹpẹrẹ ẹ̀dá sì wà fún.
Verse 58
وَٱلَّذِينَ هَاجَرُوا۟ فِى سَبِيلِ ٱللَّهِ ثُمَّ قُتِلُوٓا۟ أَوْ مَاتُوا۟ لَيَرْزُقَنَّهُمُ ٱللَّهُ رِزْقًا حَسَنًا ۚ وَإِنَّ ٱللَّهَ لَهُوَ خَيْرُ ٱلرَّٰزِقِينَ
Transliteration wa-alladhīna hājarū fī sabīli l-lahi thumma qutilū aw mātū layarzuqannahumu l-lahu riz'qan ḥasanan wa-inna l-laha lahuwa khayru l-rāziqīna
Yoruba Àwọn tí wọ́n gbé ìlú wọn jù sílẹ̀ nítorí ẹ̀sìn Allāhu, lẹ́yìn náà, tí wọ́n pa wọ́n tàbí tí wọ́n kú; dájúdájú Allāhu yóò pèsè fún wọn ní ìpèsè tó dára. Dájúdájú Allāhu, Ó mà l’óore jùlọ nínú àwọn olùpèsè.1
Verse 59
لَيُدْخِلَنَّهُم مُّدْخَلًا يَرْضَوْنَهُۥ ۗ وَإِنَّ ٱللَّهَ لَعَلِيمٌ حَلِيمٌ
Transliteration layud'khilannahum mud'khalan yarḍawnahu wa-inna l-laha laʿalīmun ḥalīmun
Yoruba Dájúdájú (Allāhu) yóò fi wọ́n sínú àyè kan tí wọn yóò yọ́nú sí. Dájúdájú Allāhu mà ni Onímọ̀, Aláfaradà.
Verse 60
۞ ذَٰلِكَ وَمَنْ عَاقَبَ بِمِثْلِ مَا عُوقِبَ بِهِۦ ثُمَّ بُغِىَ عَلَيْهِ لَيَنصُرَنَّهُ ٱللَّهُ ۗ إِنَّ ٱللَّهَ لَعَفُوٌّ غَفُورٌ
Transliteration dhālika waman ʿāqaba bimith'li mā ʿūqiba bihi thumma bughiya ʿalayhi layanṣurannahu l-lahu inna l-laha laʿafuwwun ghafūrun
Yoruba Ìyẹn (nìyẹn). Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì gbẹ̀san irú ìyà tí wọ́n fi jẹ ẹ́, lẹ́yìn náà tí wọ́n bá tún ṣàbòsí sí i, dájúdájú Allāhu yóò ṣàrànṣe fún un. Dájúdájú Allāhu mà ni Alámòjúúkúrò, Aláforíjìn.
Verse 61
ذَٰلِكَ بِأَنَّ ٱللَّهَ يُولِجُ ٱلَّيْلَ فِى ٱلنَّهَارِ وَيُولِجُ ٱلنَّهَارَ فِى ٱلَّيْلِ وَأَنَّ ٱللَّهَ سَمِيعٌۢ بَصِيرٌ
Transliteration dhālika bi-anna l-laha yūliju al-layla fī l-nahāri wayūliju l-nahāra fī al-layli wa-anna l-laha samīʿun baṣīrun
Yoruba Ìyẹn nítorí pé dájúdájú Allāhu ń fi òru bọ inú ọ̀sán, Ó sì ń fi ọ̀sán bọ inú òru. Allāhu sì ni Olùgbọ́, Olùríran.
Verse 62
ذَٰلِكَ بِأَنَّ ٱللَّهَ هُوَ ٱلْحَقُّ وَأَنَّ مَا يَدْعُونَ مِن دُونِهِۦ هُوَ ٱلْبَـٰطِلُ وَأَنَّ ٱللَّهَ هُوَ ٱلْعَلِىُّ ٱلْكَبِيرُ
Transliteration dhālika bi-anna l-laha huwa l-ḥaqu wa-anna mā yadʿūna min dūnihi huwa l-bāṭilu wa-anna l-laha huwa l-ʿaliyu l-kabīru
Yoruba Ìyẹn nítorí pé dájúdájú Allāhu, Òun ni Òdodo. Àti pé dájúdájú ohun tí wọ́n ń pè lẹ́yìn Rẹ̀ ni irọ́. Dájúdájú Allāhu, Òun ni Ó ga, Ó tóbi.
Verse 63
أَلَمْ تَرَ أَنَّ ٱللَّهَ أَنزَلَ مِنَ ٱلسَّمَآءِ مَآءً فَتُصْبِحُ ٱلْأَرْضُ مُخْضَرَّةً ۗ إِنَّ ٱللَّهَ لَطِيفٌ خَبِيرٌ
Transliteration alam tara anna l-laha anzala mina l-samāi māan fatuṣ'biḥu l-arḍu mukh'ḍarratan inna l-laha laṭīfun khabīrun
Yoruba Ṣé o ò rí i pé dájúdájú Allāhu ń sọ omi kalẹ̀ láti sánmọ̀, ilẹ̀ sì máa lọ́ràá wá? Dájúdájú Allāhu ni Aláàánú, Alámọ̀tán.
Verse 64
لَّهُۥ مَا فِى ٱلسَّمَـٰوَٰتِ وَمَا فِى ٱلْأَرْضِ ۗ وَإِنَّ ٱللَّهَ لَهُوَ ٱلْغَنِىُّ ٱلْحَمِيدُ
Transliteration lahu mā fī l-samāwāti wamā fī l-arḍi wa-inna l-laha lahuwa l-ghaniyu l-ḥamīdu
Yoruba TiRẹ̀ ni ohunkóhun tó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ohunkóhun tó wà nínú ilẹ̀. Dájúdájú Allāhu, Òun mà ni Ọlọ́rọ̀, Ẹlẹ́yìn.
Verse 65
أَلَمْ تَرَ أَنَّ ٱللَّهَ سَخَّرَ لَكُم مَّا فِى ٱلْأَرْضِ وَٱلْفُلْكَ تَجْرِى فِى ٱلْبَحْرِ بِأَمْرِهِۦ وَيُمْسِكُ ٱلسَّمَآءَ أَن تَقَعَ عَلَى ٱلْأَرْضِ إِلَّا بِإِذْنِهِۦٓ ۗ إِنَّ ٱللَّهَ بِٱلنَّاسِ لَرَءُوفٌ رَّحِيمٌ
Transliteration alam tara anna l-laha sakhara lakum mā fī l-arḍi wal-ful'ka tajrī fī l-baḥri bi-amrihi wayum'siku l-samāa an taqaʿa ʿalā l-arḍi illā bi-idh'nihi inna l-laha bil-nāsi laraūfun raḥīmun
Yoruba Ṣé o ò rí i pé dájúdájú Allāhu rọ ohunkóhun tó wà nínú ilẹ̀ fún yín, àti ọkọ̀ ojú-omi tó ń rìn nínú agbami odò pẹ̀lú àṣẹ Rẹ̀, Ó ń mú sánmọ̀ dání tí kò fi jábọ́ àyàfi pẹ̀lú ìyọ̀ǹda Rẹ̀? Dájúdájú Allāhu mà ni Aláàánú, Oníkẹ̀ẹ́ fún àwọn ènìyàn.
Verse 66
وَهُوَ ٱلَّذِىٓ أَحْيَاكُمْ ثُمَّ يُمِيتُكُمْ ثُمَّ يُحْيِيكُمْ ۗ إِنَّ ٱلْإِنسَـٰنَ لَكَفُورٌ
Transliteration wahuwa alladhī aḥyākum thumma yumītukum thumma yuḥ'yīkum inna l-insāna lakafūrun
Yoruba Òun sì ni Ẹni tó ṣe yín ni alààyè, lẹ́yìn náà Ó ń sọ yín di òkú, lẹ́yìn náà Ó máa sọ yín di alààyè. Dájúdájú ènìyàn mà ni aláìmoore.
Verse 67
لِّكُلِّ أُمَّةٍ جَعَلْنَا مَنسَكًا هُمْ نَاسِكُوهُ ۖ فَلَا يُنَـٰزِعُنَّكَ فِى ٱلْأَمْرِ ۚ وَٱدْعُ إِلَىٰ رَبِّكَ ۖ إِنَّكَ لَعَلَىٰ هُدًى مُّسْتَقِيمٍ
Transliteration likulli ummatin jaʿalnā mansakan hum nāsikūhu falā yunāziʿunnaka fī l-amri wa-ud'ʿu ilā rabbika innaka laʿalā hudan mus'taqīmin
Yoruba Ìjọ kọ̀ọ̀kan l’A fún ní ìlànà tí wọ́n máa lò. Nítorí náà, kí wọ́n má ṣe jà ọ́ níyàn nípa ọ̀rọ̀ náà. Kí o sì pèpè sọ́dọ̀ Olúwa rẹ. Dájúdájú o kúkú wà lójú ọ̀nà tààrà. 1
Verse 68
وَإِن جَـٰدَلُوكَ فَقُلِ ٱللَّهُ أَعْلَمُ بِمَا تَعْمَلُونَ
Transliteration wa-in jādalūka faquli l-lahu aʿlamu bimā taʿmalūna
Yoruba Tí wọ́n bá sì jà ọ́ níyàn, sọ nígbà náà pé: “Allāhu nímọ̀ jùlọ nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.
Verse 69
ٱللَّهُ يَحْكُمُ بَيْنَكُمْ يَوْمَ ٱلْقِيَـٰمَةِ فِيمَا كُنتُمْ فِيهِ تَخْتَلِفُونَ
Transliteration al-lahu yaḥkumu baynakum yawma l-qiyāmati fīmā kuntum fīhi takhtalifūna
Yoruba Allāhu máa ṣèdájọ́ láààrin yín ní Ọjọ́ Àjíǹde nípa ohun tí ẹ̀ ń yapa ẹnu sí.”
Verse 70
أَلَمْ تَعْلَمْ أَنَّ ٱللَّهَ يَعْلَمُ مَا فِى ٱلسَّمَآءِ وَٱلْأَرْضِ ۗ إِنَّ ذَٰلِكَ فِى كِتَـٰبٍ ۚ إِنَّ ذَٰلِكَ عَلَى ٱللَّهِ يَسِيرٌ
Transliteration alam taʿlam anna l-laha yaʿlamu mā fī l-samāi wal-arḍi inna dhālika fī kitābin inna dhālika ʿalā l-lahi yasīrun
Yoruba Ṣé o ò mọ̀ pé dájúdájú Allāhu l’Ó mọ ohun tí ń bẹ nínú sánmọ̀ àti ilẹ̀? Dájúdájú (àkọsílẹ̀) ìyẹn wà nínú tírà kan. Dájúdájú ìyẹn rọrùn fún Allāhu.
Verse 71
وَيَعْبُدُونَ مِن دُونِ ٱللَّهِ مَا لَمْ يُنَزِّلْ بِهِۦ سُلْطَـٰنًا وَمَا لَيْسَ لَهُم بِهِۦ عِلْمٌ ۗ وَمَا لِلظَّـٰلِمِينَ مِن نَّصِيرٍ
Transliteration wayaʿbudūna min dūni l-lahi mā lam yunazzil bihi sul'ṭānan wamā laysa lahum bihi ʿil'mun wamā lilẓẓālimīna min naṣīrin
Yoruba Lẹ́yìn Allāhu, wọ́n sì ń jọ́sìn fún ohun tí (Allāhu) kò sọ ẹ̀rí kan kalẹ̀ fún àti ohun tí kò sí ìmọ̀ kan fún wọn lórí rẹ̀. Kò sì níí sí alárànṣe kan fún àwọn alábòsí.
Verse 72
وَإِذَا تُتْلَىٰ عَلَيْهِمْ ءَايَـٰتُنَا بَيِّنَـٰتٍ تَعْرِفُ فِى وُجُوهِ ٱلَّذِينَ كَفَرُوا۟ ٱلْمُنكَرَ ۖ يَكَادُونَ يَسْطُونَ بِٱلَّذِينَ يَتْلُونَ عَلَيْهِمْ ءَايَـٰتِنَا ۗ قُلْ أَفَأُنَبِّئُكُم بِشَرٍّ مِّن ذَٰلِكُمُ ۗ ٱلنَّارُ وَعَدَهَا ٱللَّهُ ٱلَّذِينَ كَفَرُوا۟ ۖ وَبِئْسَ ٱلْمَصِيرُ
Transliteration wa-idhā tut'lā ʿalayhim āyātunā bayyinātin taʿrifu fī wujūhi alladhīna kafarū l-munkara yakādūna yasṭūna bi-alladhīna yatlūna ʿalayhim āyātinā qul afa-unabbi-ukum bisharrin min dhālikumu l-nāru waʿadahā l-lahu alladhīna kafarū wabi'sa l-maṣīru
Yoruba Nígbà tí wọ́n bá ń ké àwọn āyah Wa tó yanjú fún wọn, o máa rí ohun tí ẹ̀mí kọ̀ (ìkorò-ojú) nínú ojú àwọn tó ṣàì gbàgbọ́; wọn sì fẹ́ẹ̀ fọwọ́ ìnira kan àwọn tí ń ké àwọn āyah Wa fún wọn. Sọ pé: “Ṣé kí n̄g fún yín ní ìró ohun tó burú ju ìyẹn? Iná tí Allāhu ṣèlérí rẹ̀ fún àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ ni. Ìkángun náà sì burú.”
Verse 73
يَـٰٓأَيُّهَا ٱلنَّاسُ ضُرِبَ مَثَلٌ فَٱسْتَمِعُوا۟ لَهُۥٓ ۚ إِنَّ ٱلَّذِينَ تَدْعُونَ مِن دُونِ ٱللَّهِ لَن يَخْلُقُوا۟ ذُبَابًا وَلَوِ ٱجْتَمَعُوا۟ لَهُۥ ۖ وَإِن يَسْلُبْهُمُ ٱلذُّبَابُ شَيْـًٔا لَّا يَسْتَنقِذُوهُ مِنْهُ ۚ ضَعُفَ ٱلطَّالِبُ وَٱلْمَطْلُوبُ
Transliteration yāayyuhā l-nāsu ḍuriba mathalun fa-is'tamiʿū lahu inna alladhīna tadʿūna min dūni l-lahi lan yakhluqū dhubāban walawi ij'tamaʿū lahu wa-in yaslub'humu l-dhubābu shayan lā yastanqidhūhu min'hu ḍaʿufa l-ṭālibu wal-maṭlūbu
Yoruba Ẹ̀yin ènìyàn, Wọ́n fi àkàwé kan lélẹ̀. Nítorí náà, ẹ tẹ́tí sí i. Dájúdájú àwọn tí ẹ̀ ń pè lẹ́yìn Allāhu, wọn kò lè dá eṣinṣin kan, wọn ìbàá para pọ̀ láti ṣe bẹ́ẹ̀. Tí eṣinṣin náà bá sì gba kiní kan mọ́ wọn lọ́wọ́, wọn kò lè gbà á padà lọ́wọ́ rẹ̀. Ọ̀lẹ ni ẹni tí ń wá n̄ǹkan (lọ́dọ̀ òrìṣà) àti (òrìṣà) tí wọ́n ń wá n̄ǹkan lọ́dọ̀ rẹ̀.
Verse 74
مَا قَدَرُوا۟ ٱللَّهَ حَقَّ قَدْرِهِۦٓ ۗ إِنَّ ٱللَّهَ لَقَوِىٌّ عَزِيزٌ
Transliteration mā qadarū l-laha ḥaqqa qadrihi inna l-laha laqawiyyun ʿazīzun
Yoruba Wọn kò bu ọ̀wọ̀ fún Allāhu ní ọ̀wọ̀ tí ó tọ́ sí I. Dájúdájú Allāhu mà ni Alágbára, Olùborí.
Verse 75
ٱللَّهُ يَصْطَفِى مِنَ ٱلْمَلَـٰٓئِكَةِ رُسُلًا وَمِنَ ٱلنَّاسِ ۚ إِنَّ ٱللَّهَ سَمِيعٌۢ بَصِيرٌ
Transliteration al-lahu yaṣṭafī mina l-malāikati rusulan wamina l-nāsi inna l-laha samīʿun baṣīrun
Yoruba Allāhu l’Ó ń ṣa àwọn kan lẹ́ṣà (láti jẹ́) Òjíṣẹ́ nínú àwọn mọlāika àti nínú àwọn ènìyàn. Dájúdájú Allāhu ni Olùgbọ́, Olùríran.1
Verse 76
يَعْلَمُ مَا بَيْنَ أَيْدِيهِمْ وَمَا خَلْفَهُمْ ۗ وَإِلَى ٱللَّهِ تُرْجَعُ ٱلْأُمُورُ
Transliteration yaʿlamu mā bayna aydīhim wamā khalfahum wa-ilā l-lahi tur'jaʿu l-umūru
Yoruba Ó mọ ohun tí ń bẹ níwájú wọn àti ní ẹ̀yìn wọn. Ọ̀dọ̀ Allāhu sì ni wọ́n máa ṣẹ́rí àwọn ọ̀rọ̀ ẹ̀dá padà sí.
Verse 77
يَـٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُوا۟ ٱرْكَعُوا۟ وَٱسْجُدُوا۟ وَٱعْبُدُوا۟ رَبَّكُمْ وَٱفْعَلُوا۟ ٱلْخَيْرَ لَعَلَّكُمْ تُفْلِحُونَ ۩
Transliteration yāayyuhā alladhīna āmanū ir'kaʿū wa-us'judū wa-uʿ'budū rabbakum wa-if'ʿalū l-khayra laʿallakum tuf'liḥūna
Yoruba Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ dáwọ́tẹ orúnkún (lórí ìrun), ẹ forí kanlẹ̀, ẹ jọ́sìn fún Olúwa yín, kí ẹ sì ṣe rere nítorí kí ẹ lè jèrè.
Verse 78
وَجَـٰهِدُوا۟ فِى ٱللَّهِ حَقَّ جِهَادِهِۦ ۚ هُوَ ٱجْتَبَىٰكُمْ وَمَا جَعَلَ عَلَيْكُمْ فِى ٱلدِّينِ مِنْ حَرَجٍ ۚ مِّلَّةَ أَبِيكُمْ إِبْرَٰهِيمَ ۚ هُوَ سَمَّىٰكُمُ ٱلْمُسْلِمِينَ مِن قَبْلُ وَفِى هَـٰذَا لِيَكُونَ ٱلرَّسُولُ شَهِيدًا عَلَيْكُمْ وَتَكُونُوا۟ شُهَدَآءَ عَلَى ٱلنَّاسِ ۚ فَأَقِيمُوا۟ ٱلصَّلَوٰةَ وَءَاتُوا۟ ٱلزَّكَوٰةَ وَٱعْتَصِمُوا۟ بِٱللَّهِ هُوَ مَوْلَىٰكُمْ ۖ فَنِعْمَ ٱلْمَوْلَىٰ وَنِعْمَ ٱلنَّصِيرُ
Transliteration wajāhidū fī l-lahi ḥaqqa jihādihi huwa ij'tabākum wamā jaʿala ʿalaykum fī l-dīni min ḥarajin millata abīkum ib'rāhīma huwa sammākumu l-mus'limīna min qablu wafī hādhā liyakūna l-rasūlu shahīdan ʿalaykum watakūnū shuhadāa ʿalā l-nāsi fa-aqīmū l-ṣalata waātū l-zakata wa-iʿ'taṣimū bil-lahi huwa mawlākum faniʿ'ma l-mawlā waniʿ'ma l-naṣīru
Yoruba Ẹ jagun fún ẹ̀sìn Allāhu ní ọ̀nà ẹ̀tọ́ tí ẹ lè gbà jagun fún Un. Òun l’Ó ṣà yín lẹ́ṣà, kò sì kó ìdààmú kan kan ba yín nínú ẹ̀sìn. (Ẹ tẹ̀lé) ẹ̀sìn bàbá yín (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm. (Allāhu) l’Ó sọ yín ní mùsùlùmí ṣíwájú (àsìkò yìí) àti nínú (al-Ƙur’ān) yìí nítorí kí Òjíṣẹ́ lè jẹ́ ẹlẹ́rìí fún yín àti nítorí kí ẹ̀yin náà lè jẹ́ ẹlẹ́rìí fún àwọn ènìyàn.Nítorí náà, ẹ kírun, ẹ yọ Zakāh, kí ẹ sì bá Allāhu dúró. Òun ni Aláàbò yín. Ó dára ni Aláàbò. Ó sì dára ní Alárànṣe.
Read Surah Al-Hajj in another language
- English (word by word)
- Albanian
- Amazigh
- Amharic
- Assamese
- Azerbaijani
- Bambara
- Bangla
- Bosnian
- Bulgarian
- Chechen
- Chinese
- Czech
- Dari
- Dhivehi
- Dutch
- Finnish
- French
- German
- Gujarati
- Hausa
- Hebrew
- Hindi
- Indonesian
- Italian
- Japanese
- Kannada
- Kazakh
- Khmer
- Kinyarwanda
- Korean
- Kurdish
- Luganda
- Malay
- Malayalam
- Maranao
- Marathi
- Nepali
- Norwegian
- Oromo
- Pashto
- Persian
- Polish
- Portuguese
- Romanian
- Russian
- Sindhi
- Sinhala
- Somali
- Spanish
- Swahili
- Swedish
- Tagalog
- Tajik
- Tamil
- Tatar
- Telugu
- Thai
- Turkish
- Ukrainian
- Urdu
- Uyghur
- Uzbek
- Vietnamese
- Yao
All 114 surahs in Yoruba: the Qur’an in Yoruba.
Yoruba translation: Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni, from Quran.com. Transliteration: Quran.com. Recitation: Mishary Alafasy, from EveryAyah.com. MyDugsi is a learning aid, not a replacement for a qualified teacher.