Surah Al-Fajr in Yoruba: translation and audio
Surah 89 · الفجر · The Dawn · 30 verses
Surah Al-Fajr verse by verse: the Arabic with a recitation you can repeat, the transliteration, and the Yoruba translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni. For the meaning of every word, see Surah Al-Fajr word by word in English.
Verse 1
وَٱلْفَجْرِ
Transliteration wal-fajri
Yoruba Allāhu fi àfẹ̀mọ́júmọ́ búra.
Verse 2
وَلَيَالٍ عَشْرٍ
Transliteration walayālin ʿashrin
Yoruba Ó tún fi àwọn òru mẹ́wàá kan búra.
Verse 3
وَٱلشَّفْعِ وَٱلْوَتْرِ
Transliteration wal-shafʿi wal-watri
Yoruba Ó tún fi n̄ǹkan tí eéjì ń pín geerege àti n̄ǹkan tí eéjì kò pín geerege búra.
Verse 4
وَٱلَّيْلِ إِذَا يَسْرِ
Transliteration wa-al-layli idhā yasri
Yoruba Ó tún fi òru nígbà tí ó bá dé búra.
Verse 5
هَلْ فِى ذَٰلِكَ قَسَمٌ لِّذِى حِجْرٍ
Transliteration hal fī dhālika qasamun lidhī ḥij'rin
Yoruba Ǹjẹ́ ìbúra wà nínú ìyẹn fún onílàákàyè?
Verse 6
أَلَمْ تَرَ كَيْفَ فَعَلَ رَبُّكَ بِعَادٍ
Transliteration alam tara kayfa faʿala rabbuka biʿādin
Yoruba Ṣé o kò wòye sí bí Olúwa rẹ ti ṣe ọ̀rọ̀ ará ‘Ād,
Verse 7
إِرَمَ ذَاتِ ٱلْعِمَادِ
Transliteration irama dhāti l-ʿimādi
Yoruba (ìyẹn àwọn ìran) ’Irọm, àwọn òmìrán,
Verse 8
ٱلَّتِى لَمْ يُخْلَقْ مِثْلُهَا فِى ٱلْبِلَـٰدِ
Transliteration allatī lam yukh'laq mith'luhā fī l-bilādi
Yoruba àwọn tí A kò dá irú wọn mọ́ sínú ìlú?
Verse 9
وَثَمُودَ ٱلَّذِينَ جَابُوا۟ ٱلصَّخْرَ بِٱلْوَادِ
Transliteration wathamūda alladhīna jābū l-ṣakhra bil-wādi
Yoruba Àti àwọn Thamūd tí wọ́n gbẹ́ (ilé ìgbé) sínú àpáta nínú àfonúfojì,
Verse 10
وَفِرْعَوْنَ ذِى ٱلْأَوْتَادِ
Transliteration wafir'ʿawna dhī l-awtādi
Yoruba àti Fir‘aon eléèkàn (ìyà)?
Verse 11
ٱلَّذِينَ طَغَوْا۟ فِى ٱلْبِلَـٰدِ
Transliteration alladhīna ṭaghaw fī l-bilādi
Yoruba (Àwọn wọ̀nyí ni) àwọn tó tayọ ẹnu-ààlà nínú ìlú.
Verse 12
فَأَكْثَرُوا۟ فِيهَا ٱلْفَسَادَ
Transliteration fa-aktharū fīhā l-fasāda
Yoruba Wọ́n sì ṣe ìbàjẹ́ púpọ̀ sínú rẹ̀.
Verse 13
فَصَبَّ عَلَيْهِمْ رَبُّكَ سَوْطَ عَذَابٍ
Transliteration faṣabba ʿalayhim rabbuka sawṭa ʿadhābin
Yoruba Olúwa rẹ sì rọ̀jò ìyà lé wọn lórí.
Verse 14
إِنَّ رَبَّكَ لَبِٱلْمِرْصَادِ
Transliteration inna rabbaka labil-mir'ṣādi
Yoruba Dájúdájú Olúwa rẹ wà ní ibùṣọ́ (iṣẹ́ ẹ̀dá).
Verse 15
فَأَمَّا ٱلْإِنسَـٰنُ إِذَا مَا ٱبْتَلَىٰهُ رَبُّهُۥ فَأَكْرَمَهُۥ وَنَعَّمَهُۥ فَيَقُولُ رَبِّىٓ أَكْرَمَنِ
Transliteration fa-ammā l-insānu idhā mā ib'talāhu rabbuhu fa-akramahu wanaʿʿamahu fayaqūlu rabbī akramani
Yoruba Nítorí náà, ní ti ènìyàn, nígbà tí Olúwa rẹ̀ bá dán an wò, tí Ó pọ́n ọn lé, tí Ó sì ṣe ìdẹ̀ra fún un, nígbà náà ó máa wí pé: “Olúwa mi ti pọ́n mi lé.”
Verse 16
وَأَمَّآ إِذَا مَا ٱبْتَلَىٰهُ فَقَدَرَ عَلَيْهِ رِزْقَهُۥ فَيَقُولُ رَبِّىٓ أَهَـٰنَنِ
Transliteration wa-ammā idhā mā ib'talāhu faqadara ʿalayhi riz'qahu fayaqūlu rabbī ahānani
Yoruba Ṣùgbọ́n nígbà tí Ó bá dán an wò, tí Ó gán arísìkí rẹ̀ lé e lọ́wọ́, nígbà náà ó máa wí pé: “Olúwa mi ti yẹpẹrẹ mi.”
Verse 17
كَلَّا ۖ بَل لَّا تُكْرِمُونَ ٱلْيَتِيمَ
Transliteration kallā bal lā tuk'rimūna l-yatīma
Yoruba Rárá, kò rí bẹ́ẹ̀, bí kò ṣe pé, ẹ̀yin kò ṣàpọ́nlé ọmọ-òrukàn.
Verse 18
وَلَا تَحَـٰٓضُّونَ عَلَىٰ طَعَامِ ٱلْمِسْكِينِ
Transliteration walā taḥāḍḍūna ʿalā ṭaʿāmi l-mis'kīni
Yoruba Àti pé ẹ̀yin kò gbẹra yín lóǹgbẹ láti fún mẹ̀kúnnù ní oúnjẹ.
Verse 19
وَتَأْكُلُونَ ٱلتُّرَاثَ أَكْلًا لَّمًّا
Transliteration watakulūna l-turātha aklan lamman
Yoruba Ẹ tún ń jẹ ogún ní ìjẹkújẹ.
Verse 20
وَتُحِبُّونَ ٱلْمَالَ حُبًّا جَمًّا
Transliteration watuḥibbūna l-māla ḥubban jamman
Yoruba Àti pé ẹ nífẹ̀ẹ́ sí dúkìá ní ìfẹ́ púpọ̀.
Verse 21
كَلَّآ إِذَا دُكَّتِ ٱلْأَرْضُ دَكًّا دَكًّا
Transliteration kallā idhā dukkati l-arḍu dakkan dakkan
Yoruba Rárá, (kò yẹ kó rí bẹ́ẹ̀). Nígbà tí wọ́n bá mi ilẹ̀ tìtì ní mímì tìtì (tó rún wómúwómú, tí kò sí kòtò, tí kò sí gelemọ),
Verse 22
وَجَآءَ رَبُّكَ وَٱلْمَلَكُ صَفًّا صَفًّا
Transliteration wajāa rabbuka wal-malaku ṣaffan ṣaffan
Yoruba (tí) Olúwa rẹ dé pẹ̀lú àwọn mọlāika ní ọ̀wọ̀ọ̀wọ́ ọ̀wọ̀ọ̀wọ́,
Verse 23
وَجِا۟ىٓءَ يَوْمَئِذٍۭ بِجَهَنَّمَ ۚ يَوْمَئِذٍ يَتَذَكَّرُ ٱلْإِنسَـٰنُ وَأَنَّىٰ لَهُ ٱلذِّكْرَىٰ
Transliteration wajīa yawma-idhin bijahannama yawma-idhin yatadhakkaru l-insānu wa-annā lahu l-dhik'rā
Yoruba ní ọjọ́ yẹn ni wọ́n máa mú iná Jahanamọ wá. Ní ọjọ́ yẹn, ènìyàn yóò rántí (ọ̀rọ̀ ara rẹ̀). Báwo sì ni ìrántí náà ṣe lè wúlò fún un!
Verse 24
يَقُولُ يَـٰلَيْتَنِى قَدَّمْتُ لِحَيَاتِى
Transliteration yaqūlu yālaytanī qaddamtu liḥayātī
Yoruba Ó máa wí pé: “Yéè, èmi ìbá ti ti (iṣẹ́ rere) síwájú fún ìṣẹ̀mí mi.”
Verse 25
فَيَوْمَئِذٍ لَّا يُعَذِّبُ عَذَابَهُۥٓ أَحَدٌ
Transliteration fayawma-idhin lā yuʿadhibu ʿadhābahu aḥadun
Yoruba Ní ọjọ́ yẹn, ẹnì kan kò lè fi ìyà jẹ (ẹ̀dá) bí irú ìyà (tí) Allāhu (yóò fi jẹ ẹ́).
Verse 26
وَلَا يُوثِقُ وَثَاقَهُۥٓ أَحَدٌ
Transliteration walā yūthiqu wathāqahu aḥadun
Yoruba Ẹnì kan kò sì lè de (ẹ̀dá) ní ìgbèkùn bí irú ìgbèkùn (tí) Allāhu (yóò fi dè é).
Verse 27
يَـٰٓأَيَّتُهَا ٱلنَّفْسُ ٱلْمُطْمَئِنَّةُ
Transliteration yāayyatuhā l-nafsu l-muṭ'ma-inatu
Yoruba Ìwọ ẹ̀mí olùfọ̀kànbalẹ̀,
Verse 28
ٱرْجِعِىٓ إِلَىٰ رَبِّكِ رَاضِيَةً مَّرْضِيَّةً
Transliteration ir'jiʿī ilā rabbiki rāḍiyatan marḍiyyatan
Yoruba padà sí ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ ní olùyọ́nú, ẹni ìyọ́nú.
Verse 29
فَٱدْخُلِى فِى عِبَـٰدِى
Transliteration fa-ud'khulī fī ʿibādī
Yoruba Nítorí náà, wọlé sáààrin àwọn ẹrúsìn Mi.
Verse 30
وَٱدْخُلِى جَنَّتِى
Transliteration wa-ud'khulī jannatī
Yoruba Wọ inú Ọgbà Ìdẹ̀ra Mi.
Read Surah Al-Fajr in another language
- English (word by word)
- Albanian
- Amazigh
- Amharic
- Assamese
- Azerbaijani
- Bambara
- Bangla
- Bosnian
- Bulgarian
- Chechen
- Chinese
- Czech
- Dari
- Dhivehi
- Dutch
- Finnish
- French
- German
- Gujarati
- Hausa
- Hebrew
- Hindi
- Indonesian
- Italian
- Japanese
- Kannada
- Kazakh
- Khmer
- Kinyarwanda
- Korean
- Kurdish
- Luganda
- Malay
- Malayalam
- Maranao
- Marathi
- Nepali
- Norwegian
- Oromo
- Pashto
- Persian
- Polish
- Portuguese
- Romanian
- Russian
- Sindhi
- Sinhala
- Somali
- Spanish
- Swahili
- Swedish
- Tagalog
- Tajik
- Tamil
- Tatar
- Telugu
- Thai
- Turkish
- Ukrainian
- Urdu
- Uyghur
- Uzbek
- Vietnamese
- Yao
All 114 surahs in Yoruba: the Qur’an in Yoruba.
Yoruba translation: Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni, from Quran.com. Transliteration: Quran.com. Recitation: Mishary Alafasy, from EveryAyah.com. MyDugsi is a learning aid, not a replacement for a qualified teacher.