Surah Al-'Ankabut in Yoruba: translation and audio
Surah 29 · العنكبوت · The Spider · 69 verses
Surah Al-'Ankabut verse by verse: the Arabic with a recitation you can repeat, the transliteration, and the Yoruba translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni. For the meaning of every word, see Surah Al-'Ankabut word by word in English.
Verse 1
الٓمٓ
Transliteration alif-lam-meem
Yoruba ’Alif lām mīm. (Allāhu ló mọ ohun tí Ó gbàlérò pẹ̀lú àwọn háràfí náà.)1
Verse 2
أَحَسِبَ ٱلنَّاسُ أَن يُتْرَكُوٓا۟ أَن يَقُولُوٓا۟ ءَامَنَّا وَهُمْ لَا يُفْتَنُونَ
Transliteration aḥasiba l-nāsu an yut'rakū an yaqūlū āmannā wahum lā yuf'tanūna
Yoruba Ǹjẹ́ àwọn ènìyàn lérò pé A óò fi wọ́n sílẹ̀ kí wọ́n máa sọ pé: “A gbàgbọ́”, tí A ò sì níí dán wọn wò?
Verse 3
وَلَقَدْ فَتَنَّا ٱلَّذِينَ مِن قَبْلِهِمْ ۖ فَلَيَعْلَمَنَّ ٱللَّهُ ٱلَّذِينَ صَدَقُوا۟ وَلَيَعْلَمَنَّ ٱلْكَـٰذِبِينَ
Transliteration walaqad fatannā alladhīna min qablihim falayaʿlamanna l-lahu alladhīna ṣadaqū walayaʿlamanna l-kādhibīna
Yoruba A kúkú ti dán àwọn tó ṣíwájú wọn wò. Nítorí náà, dájúdájú Allāhu máa ṣàfi hàn àwọn tó sọ òdodo. Dájúdájú Ó sì máa ṣàfi hàn àwọn òpùrọ́.
Verse 4
أَمْ حَسِبَ ٱلَّذِينَ يَعْمَلُونَ ٱلسَّيِّـَٔاتِ أَن يَسْبِقُونَا ۚ سَآءَ مَا يَحْكُمُونَ
Transliteration am ḥasiba alladhīna yaʿmalūna l-sayiāti an yasbiqūnā sāa mā yaḥkumūna
Yoruba Àbí àwọn tó ń ṣe iṣẹ́ aburú lérò pé àwọn máa mórí bọ́ mọ́ Wa lọ́wọ́ ni? Ohun tí wọ́n ń dá lẹ́jọ́ burú.
Verse 5
مَن كَانَ يَرْجُوا۟ لِقَآءَ ٱللَّهِ فَإِنَّ أَجَلَ ٱللَّهِ لَـَٔاتٍ ۚ وَهُوَ ٱلسَّمِيعُ ٱلْعَلِيمُ
Transliteration man kāna yarjū liqāa l-lahi fa-inna ajala l-lahi laātin wahuwa l-samīʿu l-ʿalīmu
Yoruba Ẹnikẹ́ni tí ó bá ń retí ìpàdé Allāhu, dájúdájú àkókò Allāhu kúkú ń bọ̀. Òun sì ni Olùgbọ́, Onímọ̀.
Verse 6
وَمَن جَـٰهَدَ فَإِنَّمَا يُجَـٰهِدُ لِنَفْسِهِۦٓ ۚ إِنَّ ٱللَّهَ لَغَنِىٌّ عَنِ ٱلْعَـٰلَمِينَ
Transliteration waman jāhada fa-innamā yujāhidu linafsihi inna l-laha laghaniyyun ʿani l-ʿālamīna
Yoruba Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbìyànjú, ó ń gbìyànjú fún ẹ̀mí ara rẹ̀ ni. Dájúdájú Allāhu ni Ọlọ́rọ̀ tí kò bùkátà sí gbogbo ẹ̀dá.
Verse 7
وَٱلَّذِينَ ءَامَنُوا۟ وَعَمِلُوا۟ ٱلصَّـٰلِحَـٰتِ لَنُكَفِّرَنَّ عَنْهُمْ سَيِّـَٔاتِهِمْ وَلَنَجْزِيَنَّهُمْ أَحْسَنَ ٱلَّذِى كَانُوا۟ يَعْمَلُونَ
Transliteration wa-alladhīna āmanū waʿamilū l-ṣāliḥāti lanukaffiranna ʿanhum sayyiātihim walanajziyannahum aḥsana alladhī kānū yaʿmalūna
Yoruba Àwọn tó bá gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe iṣẹ́ rere, dájúdájú A máa ha àwọn iṣẹ́ aburú wọn dànù fún wọn. Dájúdájú A ó sì san wọ́n lẹ́san pẹ̀lú èyí tó dára ju ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́.
Verse 8
وَوَصَّيْنَا ٱلْإِنسَـٰنَ بِوَٰلِدَيْهِ حُسْنًا ۖ وَإِن جَـٰهَدَاكَ لِتُشْرِكَ بِى مَا لَيْسَ لَكَ بِهِۦ عِلْمٌ فَلَا تُطِعْهُمَآ ۚ إِلَىَّ مَرْجِعُكُمْ فَأُنَبِّئُكُم بِمَا كُنتُمْ تَعْمَلُونَ
Transliteration wawaṣṣaynā l-insāna biwālidayhi ḥus'nan wa-in jāhadāka litush'rika bī mā laysa laka bihi ʿil'mun falā tuṭiʿ'humā ilayya marjiʿukum fa-unabbi-ukum bimā kuntum taʿmalūna
Yoruba A pa á ní àṣẹ fún ènìyàn láti ṣe dáadáa sí àwọn òbí rẹ̀ méjèèjì. Tí àwọn méjèèjì bá sì jà ọ́ lógun pé kí ó fi ohun tí ìwọ kò ní ìmọ̀ nípa rẹ̀ ṣẹbọ sí Mi, má ṣe tẹ̀lé àwọn méjèèjì.Ọ̀dọ̀ Mi ni ibùpadàsí yín. Nítorí náà, Mo máa fún yín ní ìró ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.
Verse 9
وَٱلَّذِينَ ءَامَنُوا۟ وَعَمِلُوا۟ ٱلصَّـٰلِحَـٰتِ لَنُدْخِلَنَّهُمْ فِى ٱلصَّـٰلِحِينَ
Transliteration wa-alladhīna āmanū waʿamilū l-ṣāliḥāti lanud'khilannahum fī l-ṣāliḥīna
Yoruba Àwọn tó bá gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe iṣẹ́ rere, dájúdájú A máa fi wọ́n sínú àwọn ẹni rere.
Verse 10
وَمِنَ ٱلنَّاسِ مَن يَقُولُ ءَامَنَّا بِٱللَّهِ فَإِذَآ أُوذِىَ فِى ٱللَّهِ جَعَلَ فِتْنَةَ ٱلنَّاسِ كَعَذَابِ ٱللَّهِ وَلَئِن جَآءَ نَصْرٌ مِّن رَّبِّكَ لَيَقُولُنَّ إِنَّا كُنَّا مَعَكُمْ ۚ أَوَلَيْسَ ٱللَّهُ بِأَعْلَمَ بِمَا فِى صُدُورِ ٱلْعَـٰلَمِينَ
Transliteration wamina l-nāsi man yaqūlu āmannā bil-lahi fa-idhā ūdhiya fī l-lahi jaʿala fit'nata l-nāsi kaʿadhābi l-lahi wala-in jāa naṣrun min rabbika layaqūlunna innā kunnā maʿakum awalaysa l-lahu bi-aʿlama bimā fī ṣudūri l-ʿālamīna
Yoruba Ó ń bẹ nínú àwọn ènìyàn, ẹni tó ń wí pé: “A gba Allāhu gbọ́.” Nígbà tí wọ́n bá sì fi ìnira kàn án nínú ẹ̀sìn Allāhu, ó máa mú ìnira àwọn ènìyàn gẹ́gẹ́ bí ìyà ti Allāhu. (Ó sì máa padà sínú àìgbàgbọ́.) Tí àrànṣe kan láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ bá sì dé, dájúdájú wọn yóò wí pé: “Dájúdájú àwa wà pẹ̀lú yín.” Ṣé Allāhu kọ́ l’Ó nímọ̀ jùlọ nípa ohun tí ń bẹ nínú igbá-àyà gbogbo ẹ̀dá ni?
Verse 11
وَلَيَعْلَمَنَّ ٱللَّهُ ٱلَّذِينَ ءَامَنُوا۟ وَلَيَعْلَمَنَّ ٱلْمُنَـٰفِقِينَ
Transliteration walayaʿlamanna l-lahu alladhīna āmanū walayaʿlamanna l-munāfiqīna
Yoruba Dájúdájú Allāhu máa ṣàfi hàn àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo. Ó sì máa ṣàfi hàn àwọn ṣọ̀be-ṣèlu mùsùlùmí.
Verse 12
وَقَالَ ٱلَّذِينَ كَفَرُوا۟ لِلَّذِينَ ءَامَنُوا۟ ٱتَّبِعُوا۟ سَبِيلَنَا وَلْنَحْمِلْ خَطَـٰيَـٰكُمْ وَمَا هُم بِحَـٰمِلِينَ مِنْ خَطَـٰيَـٰهُم مِّن شَىْءٍ ۖ إِنَّهُمْ لَكَـٰذِبُونَ
Transliteration waqāla alladhīna kafarū lilladhīna āmanū ittabiʿū sabīlanā walnaḥmil khaṭāyākum wamā hum biḥāmilīna min khaṭāyāhum min shayin innahum lakādhibūna
Yoruba Àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ wí fún àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo pé: “Ẹ tẹ̀lé ojú ọ̀nà tiwa nítorí kí á lè ru àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín.” Wọn kò sì lè ru kiní kan nínú ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Dájúdájú òpùrọ́ mà ni wọ́n.
Verse 13
وَلَيَحْمِلُنَّ أَثْقَالَهُمْ وَأَثْقَالًا مَّعَ أَثْقَالِهِمْ ۖ وَلَيُسْـَٔلُنَّ يَوْمَ ٱلْقِيَـٰمَةِ عَمَّا كَانُوا۟ يَفْتَرُونَ
Transliteration walayaḥmilunna athqālahum wa-athqālan maʿa athqālihim walayus'alunna yawma l-qiyāmati ʿammā kānū yaftarūna
Yoruba Dájúdájú wọn yóò ru ẹrù ẹ̀ṣẹ̀ tiwọn àti àwọn ẹrù ẹ̀ṣẹ̀ kan mọ́ ẹrù ẹ̀ṣẹ̀ tiwọn. Àti pé dájúdájú A óò bi wọ́n léèrè ní Ọjọ́ Àjíǹde nípa ohun tí wọ́n ń dá ní àdápa irọ́.1
Verse 14
وَلَقَدْ أَرْسَلْنَا نُوحًا إِلَىٰ قَوْمِهِۦ فَلَبِثَ فِيهِمْ أَلْفَ سَنَةٍ إِلَّا خَمْسِينَ عَامًا فَأَخَذَهُمُ ٱلطُّوفَانُ وَهُمْ ظَـٰلِمُونَ
Transliteration walaqad arsalnā nūḥan ilā qawmihi falabitha fīhim alfa sanatin illā khamsīna ʿāman fa-akhadhahumu l-ṭūfānu wahum ẓālimūna
Yoruba Dájúdájú A rán (Ànábì) Nūh níṣẹ́ sí ìjọ rẹ̀. Ó gbé láààrin wọn fún ẹgbẹ̀rún ọdún àfi àádọ́ta ọdún. Ẹ̀kún-omi sì gbá wọn mú nígbà tí wọ́n jẹ́ alábòsí.
Verse 15
فَأَنجَيْنَـٰهُ وَأَصْحَـٰبَ ٱلسَّفِينَةِ وَجَعَلْنَـٰهَآ ءَايَةً لِّلْعَـٰلَمِينَ
Transliteration fa-anjaynāhu wa-aṣḥāba l-safīnati wajaʿalnāhā āyatan lil'ʿālamīna
Yoruba A sì la òun àti àwọn èrò inú ọkọ̀ ojú-omi. A sì ṣe wọ́n ní àmì fún gbogbo ẹ̀dá.1
Verse 16
وَإِبْرَٰهِيمَ إِذْ قَالَ لِقَوْمِهِ ٱعْبُدُوا۟ ٱللَّهَ وَٱتَّقُوهُ ۖ ذَٰلِكُمْ خَيْرٌ لَّكُمْ إِن كُنتُمْ تَعْلَمُونَ
Transliteration wa-ib'rāhīma idh qāla liqawmihi uʿ'budū l-laha wa-ittaqūhu dhālikum khayrun lakum in kuntum taʿlamūna
Yoruba (Rántí Ànábì) ’Ibrọ̄hīm. Nígbà tí ó sọ fún ìjọ rẹ̀ pé: “Ẹ jọ́sìn fún Allāhu. Kí ẹ sì páyà Rẹ̀. Ìyẹn lóore jùlọ fún yín tí ẹ bá mọ̀.”
Verse 17
إِنَّمَا تَعْبُدُونَ مِن دُونِ ٱللَّهِ أَوْثَـٰنًا وَتَخْلُقُونَ إِفْكًا ۚ إِنَّ ٱلَّذِينَ تَعْبُدُونَ مِن دُونِ ٱللَّهِ لَا يَمْلِكُونَ لَكُمْ رِزْقًا فَٱبْتَغُوا۟ عِندَ ٱللَّهِ ٱلرِّزْقَ وَٱعْبُدُوهُ وَٱشْكُرُوا۟ لَهُۥٓ ۖ إِلَيْهِ تُرْجَعُونَ
Transliteration innamā taʿbudūna min dūni l-lahi awthānan watakhluqūna if'kan inna alladhīna taʿbudūna min dūni l-lahi lā yamlikūna lakum riz'qan fa-ib'taghū ʿinda l-lahi l-riz'qa wa-uʿ'budūhu wa-ush'kurū lahu ilayhi tur'jaʿūna
Yoruba Ẹ kàn ń jọ́sìn fún àwọn òrìṣà lẹ́yìn Allāhu. Ẹ sì ń dá àdápa irọ́. Dájúdájú àwọn tí ẹ̀ ń jọ́sìn fún lẹ́yìn Allāhu, wọn kò ní ìkápá arísìkí kan fún yín. Ẹ wá arísìkí sí ọ̀dọ̀ Allāhu. Kí ẹ jọ́sìn fún Un. Kí ẹ sì dúpẹ́ fún Un. Ọ̀dọ̀ Rẹ̀ ni wọn yóò da yín padà sí.
Verse 18
وَإِن تُكَذِّبُوا۟ فَقَدْ كَذَّبَ أُمَمٌ مِّن قَبْلِكُمْ ۖ وَمَا عَلَى ٱلرَّسُولِ إِلَّا ٱلْبَلَـٰغُ ٱلْمُبِينُ
Transliteration wa-in tukadhibū faqad kadhaba umamun min qablikum wamā ʿalā l-rasūli illā l-balāghu l-mubīnu
Yoruba Tí ẹ bá sì pe (òdodo) ní irọ́, àwọn ìjọ kan tó ṣíwájú yín kúkú ti pe (òdodo) ní irọ́. Kò sì sí ojúṣe kan fún Òjíṣẹ́ bí kò ṣe ìkéde (ẹ̀sìn) tó yanjú.
Verse 19
أَوَلَمْ يَرَوْا۟ كَيْفَ يُبْدِئُ ٱللَّهُ ٱلْخَلْقَ ثُمَّ يُعِيدُهُۥٓ ۚ إِنَّ ذَٰلِكَ عَلَى ٱللَّهِ يَسِيرٌ
Transliteration awalam yaraw kayfa yub'di-u l-lahu l-khalqa thumma yuʿīduhu inna dhālika ʿalā l-lahi yasīrun
Yoruba Tàbí wọn kò wòye sí bí Allāhu ti ṣe bẹ̀rẹ̀ ẹ̀dá ni? Lẹ́yìn náà, O máa dá a padà (sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀). Dájúdájú ìyẹn rọrùn fún Allāhu.
Verse 20
قُلْ سِيرُوا۟ فِى ٱلْأَرْضِ فَٱنظُرُوا۟ كَيْفَ بَدَأَ ٱلْخَلْقَ ۚ ثُمَّ ٱللَّهُ يُنشِئُ ٱلنَّشْأَةَ ٱلْـَٔاخِرَةَ ۚ إِنَّ ٱللَّهَ عَلَىٰ كُلِّ شَىْءٍ قَدِيرٌ
Transliteration qul sīrū fī l-arḍi fa-unẓurū kayfa bada-a l-khalqa thumma l-lahu yunshi-u l-nashata l-ākhirata inna l-laha ʿalā kulli shayin qadīrun
Yoruba Sọ pé: “Ẹ rìn kiri lórí ilẹ̀, kí ẹ wo bí Ó ṣe bẹ̀rẹ̀ ẹ̀dá (ní ìpìlẹ̀). Lẹ́yìn náà, Allāhu l’Ó máa mú ìṣẹ̀dá ìkẹ́yìn wá (fún àjíǹde). Dájúdájú Allāhu ni Alágbára lórí gbogbo n̄ǹkan.”
Verse 21
يُعَذِّبُ مَن يَشَآءُ وَيَرْحَمُ مَن يَشَآءُ ۖ وَإِلَيْهِ تُقْلَبُونَ
Transliteration yuʿadhibu man yashāu wayarḥamu man yashāu wa-ilayhi tuq'labūna
Yoruba Ó ń jẹ ẹni tí Ó bá fẹ́ níyà. Ó sì ń kẹ́ ẹni tí Ó bá fẹ́. Ọ̀dọ̀ Rẹ̀ sì ni wọn yóò da yín padà sí.1
Verse 22
وَمَآ أَنتُم بِمُعْجِزِينَ فِى ٱلْأَرْضِ وَلَا فِى ٱلسَّمَآءِ ۖ وَمَا لَكُم مِّن دُونِ ٱللَّهِ مِن وَلِىٍّ وَلَا نَصِيرٍ
Transliteration wamā antum bimuʿ'jizīna fī l-arḍi walā fī l-samāi wamā lakum min dūni l-lahi min waliyyin walā naṣīrin
Yoruba Àti pé ẹ̀yin kò níí mórí bọ́ mọ́ Allāhu lọ́wọ́ lórí ilẹ̀ àti nínú sánmọ̀. Kò sì sí aláàbò àti alárànṣe kan fún yín lẹ́yìn Allāhu.
Verse 23
وَٱلَّذِينَ كَفَرُوا۟ بِـَٔايَـٰتِ ٱللَّهِ وَلِقَآئِهِۦٓ أُو۟لَـٰٓئِكَ يَئِسُوا۟ مِن رَّحْمَتِى وَأُو۟لَـٰٓئِكَ لَهُمْ عَذَابٌ أَلِيمٌ
Transliteration wa-alladhīna kafarū biāyāti l-lahi waliqāihi ulāika ya-isū min raḥmatī wa-ulāika lahum ʿadhābun alīmun
Yoruba Àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ nínú àwọn āyah Allāhu àti ìpàdé Rẹ̀ (lọ́run), àwọn wọ̀nyẹn ti sọ̀rètí nù nínú ìkẹ́ Mi. Àwọn wọ̀nyẹn ni ìyà ẹlẹ́ta-eléro ń bẹ fún.
Verse 24
فَمَا كَانَ جَوَابَ قَوْمِهِۦٓ إِلَّآ أَن قَالُوا۟ ٱقْتُلُوهُ أَوْ حَرِّقُوهُ فَأَنجَىٰهُ ٱللَّهُ مِنَ ٱلنَّارِ ۚ إِنَّ فِى ذَٰلِكَ لَـَٔايَـٰتٍ لِّقَوْمٍ يُؤْمِنُونَ
Transliteration famā kāna jawāba qawmihi illā an qālū uq'tulūhu aw ḥarriqūhu fa-anjāhu l-lahu mina l-nāri inna fī dhālika laāyātin liqawmin yu'minūna
Yoruba Èsì ìjọ rẹ̀ kò jẹ́ kiní kan tayọ pé wọ́n wí pé: “Ẹ pa á tàbí kí ẹ sun ún níná.” Allāhu sì gbà á là nínú iná. Dájúdájú àwọn àmì kúkú wà nínú ìyẹn fún ìjọ tó gbàgbọ́ ní òdodo.
Verse 25
وَقَالَ إِنَّمَا ٱتَّخَذْتُم مِّن دُونِ ٱللَّهِ أَوْثَـٰنًا مَّوَدَّةَ بَيْنِكُمْ فِى ٱلْحَيَوٰةِ ٱلدُّنْيَا ۖ ثُمَّ يَوْمَ ٱلْقِيَـٰمَةِ يَكْفُرُ بَعْضُكُم بِبَعْضٍ وَيَلْعَنُ بَعْضُكُم بَعْضًا وَمَأْوَىٰكُمُ ٱلنَّارُ وَمَا لَكُم مِّن نَّـٰصِرِينَ
Transliteration waqāla innamā ittakhadhtum min dūni l-lahi awthānan mawaddata baynikum fī l-ḥayati l-dun'yā thumma yawma l-qiyāmati yakfuru baʿḍukum bibaʿḍin wayalʿanu baʿḍukum baʿḍan wamawākumu l-nāru wamā lakum min nāṣirīna
Yoruba Ó sì sọ pé: “Ẹ kàn mú àwọn òrìṣà lẹ́yìn Allāhu, ní ohun tí ẹ nífẹ̀ẹ́ sí (láti jọ́sìn fún) láààrin ara yín nínú ìṣẹ̀mí ayé (yìí). Lẹ́yìn náà, ní Ọjọ́ Àjíǹde apá kan yin yóò tako apá kan. Apá kan yín yó sì ṣẹ́bi lé apá kan. Iná sì ni ibùgbé yín. Kò sì níí sí àwọn alárànṣe kan fún yín.”
Verse 26
۞ فَـَٔامَنَ لَهُۥ لُوطٌ ۘ وَقَالَ إِنِّى مُهَاجِرٌ إِلَىٰ رَبِّىٓ ۖ إِنَّهُۥ هُوَ ٱلْعَزِيزُ ٱلْحَكِيمُ
Transliteration faāmana lahu lūṭun waqāla innī muhājirun ilā rabbī innahu huwa l-ʿazīzu l-ḥakīmu
Yoruba (Ànábì) Lūt sì gbà á gbọ́. (Ànábì ’Ibrọ̄hīm) sọ pé: “Dájúdájú èmi yóò fi ìlú yìí sílẹ̀ nítorí ti Olúwa mi.Dájúdájú Òun ni Alágbára, Ọlọ́gbọ́n.
Verse 27
وَوَهَبْنَا لَهُۥٓ إِسْحَـٰقَ وَيَعْقُوبَ وَجَعَلْنَا فِى ذُرِّيَّتِهِ ٱلنُّبُوَّةَ وَٱلْكِتَـٰبَ وَءَاتَيْنَـٰهُ أَجْرَهُۥ فِى ٱلدُّنْيَا ۖ وَإِنَّهُۥ فِى ٱلْـَٔاخِرَةِ لَمِنَ ٱلصَّـٰلِحِينَ
Transliteration wawahabnā lahu is'ḥāqa wayaʿqūba wajaʿalnā fī dhurriyyatihi l-nubuwata wal-kitāba waātaynāhu ajrahu fī l-dun'yā wa-innahu fī l-ākhirati lamina l-ṣāliḥīna
Yoruba A fi ’Ishāƙ àti Ya‘ƙūb (ọmọọmọ rẹ̀) ta á lọ́rẹ. A sì ṣe ipò jíjẹ́ Ànábì àti fífúnni ní tírà sínú àrọ́mọdọ́mọ rẹ̀. A fún un ní ẹ̀san rẹ̀ ní ayé yìí. Dájúdájú ní ọ̀run, ó tún wà nínú àwọn ẹni rere.
Verse 28
وَلُوطًا إِذْ قَالَ لِقَوْمِهِۦٓ إِنَّكُمْ لَتَأْتُونَ ٱلْفَـٰحِشَةَ مَا سَبَقَكُم بِهَا مِنْ أَحَدٍ مِّنَ ٱلْعَـٰلَمِينَ
Transliteration walūṭan idh qāla liqawmihi innakum latatūna l-fāḥishata mā sabaqakum bihā min aḥadin mina l-ʿālamīna
Yoruba (Rántí Ànábì) Lūt. Nígbà tí ó sọ fún ìjọ rẹ̀ pé: “Dájúdájú ẹ̀yin ń ṣe ìbàjẹ́ tí kò sí ẹnì kan nínú ẹ̀dá tí ó ṣe é rí ṣíwájú yín.
Verse 29
أَئِنَّكُمْ لَتَأْتُونَ ٱلرِّجَالَ وَتَقْطَعُونَ ٱلسَّبِيلَ وَتَأْتُونَ فِى نَادِيكُمُ ٱلْمُنكَرَ ۖ فَمَا كَانَ جَوَابَ قَوْمِهِۦٓ إِلَّآ أَن قَالُوا۟ ٱئْتِنَا بِعَذَابِ ٱللَّهِ إِن كُنتَ مِنَ ٱلصَّـٰدِقِينَ
Transliteration a-innakum latatūna l-rijāla wataqṭaʿūna l-sabīla watatūna fī nādīkumu l-munkara famā kāna jawāba qawmihi illā an qālū i'tinā biʿadhābi l-lahi in kunta mina l-ṣādiqīna
Yoruba Ṣé dájúdájú ẹ̀yin (ọkùnrin) yóò máa tọ àwọn ọkùnrin (ẹgbẹ́ yín) lọ (fún adùn ìbálòpọ̀), ẹ tún ń dánà, ẹ tún ń ṣe ohun burúkú nínú àkójọ yín? Èsì ìjọ rẹ̀ kò jẹ́ kiní kan àfi kí wọ́n wí pé “Mú ìyà Allāhu wá fún wa tí o bá wà nínú àwọn olódodo.”
Verse 30
قَالَ رَبِّ ٱنصُرْنِى عَلَى ٱلْقَوْمِ ٱلْمُفْسِدِينَ
Transliteration qāla rabbi unṣur'nī ʿalā l-qawmi l-muf'sidīna
Yoruba Ó sọ pé: “Olúwa mi, ṣàrànṣe fún mí lórí ìjọ òbìlẹ̀jẹ́.”
Verse 31
وَلَمَّا جَآءَتْ رُسُلُنَآ إِبْرَٰهِيمَ بِٱلْبُشْرَىٰ قَالُوٓا۟ إِنَّا مُهْلِكُوٓا۟ أَهْلِ هَـٰذِهِ ٱلْقَرْيَةِ ۖ إِنَّ أَهْلَهَا كَانُوا۟ ظَـٰلِمِينَ
Transliteration walammā jāat rusulunā ib'rāhīma bil-bush'rā qālū innā muh'likū ahli hādhihi l-qaryati inna ahlahā kānū ẓālimīna
Yoruba Nígbà tí àwọn Òjíṣẹ́ Wa sì mú ìró ìdùnnú dé bá (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm, wọ́n sọ pé: “Dájúdájú àwa máa pa àwọn ará ìlú yìí run. Dájúdájú àwọn ará ìlú náà jẹ́ alábòsí.”
Verse 32
قَالَ إِنَّ فِيهَا لُوطًا ۚ قَالُوا۟ نَحْنُ أَعْلَمُ بِمَن فِيهَا ۖ لَنُنَجِّيَنَّهُۥ وَأَهْلَهُۥٓ إِلَّا ٱمْرَأَتَهُۥ كَانَتْ مِنَ ٱلْغَـٰبِرِينَ
Transliteration qāla inna fīhā lūṭan qālū naḥnu aʿlamu biman fīhā lanunajjiyannahu wa-ahlahu illā im'ra-atahu kānat mina l-ghābirīna
Yoruba Ó sọ pé: “Dájúdájú (Ànábì) Lūt wà níbẹ̀! Wọ́n sọ pé: “Àwa nímọ̀ jùlọ nípa àwọn tó wà níbẹ̀. Dájúdájú àwa yóò la òun àti àwọn ará ilé rẹ̀ àfi ìyàwó rẹ̀ tí ó máa wà nínú àwọn tó máa ṣẹ́kù lẹ́yìn sínú ìparun.”
Verse 33
وَلَمَّآ أَن جَآءَتْ رُسُلُنَا لُوطًا سِىٓءَ بِهِمْ وَضَاقَ بِهِمْ ذَرْعًا وَقَالُوا۟ لَا تَخَفْ وَلَا تَحْزَنْ ۖ إِنَّا مُنَجُّوكَ وَأَهْلَكَ إِلَّا ٱمْرَأَتَكَ كَانَتْ مِنَ ٱلْغَـٰبِرِينَ
Transliteration walammā an jāat rusulunā lūṭan sīa bihim waḍāqa bihim dharʿan waqālū lā takhaf walā taḥzan innā munajjūka wa-ahlaka illā im'ra-ataka kānat mina l-ghābirīna
Yoruba Nígbà tí àwọn Òjíṣẹ́ Wa dé ọ̀dọ̀ (Ànábì) Lūt, ó banújẹ́ nítorí wọn. Agbára rẹ̀ kò sì ká ọ̀rọ̀ wọn mọ́. Wọ́n sì sọ fún un pé: “Má bẹ̀rù, má sì ṣe banújẹ́. Dájúdájú a máa la ìwọ àti àwọn ará ilé rẹ àfi ìyàwó rẹ tí ó máa wà nínú àwọn olùṣẹ́kù-lẹ́yìn sínú ìparun.”
Verse 34
إِنَّا مُنزِلُونَ عَلَىٰٓ أَهْلِ هَـٰذِهِ ٱلْقَرْيَةِ رِجْزًا مِّنَ ٱلسَّمَآءِ بِمَا كَانُوا۟ يَفْسُقُونَ
Transliteration innā munzilūna ʿalā ahli hādhihi l-qaryati rij'zan mina l-samāi bimā kānū yafsuqūna
Yoruba Dájúdájú a máa sọ ìyà kan kalẹ̀ lé àwọn ará ìlú yìí lórí láti inú sánmọ̀ nítorí pé, wọ́n jẹ́ òbìlẹ̀jẹ́.
Verse 35
وَلَقَد تَّرَكْنَا مِنْهَآ ءَايَةًۢ بَيِّنَةً لِّقَوْمٍ يَعْقِلُونَ
Transliteration walaqad taraknā min'hā āyatan bayyinatan liqawmin yaʿqilūna
Yoruba Dájúdájú A ti fi àmì kan tó fojú hàn lélẹ̀ nínú rẹ̀ fún ìjọ tó ní làákàyè.
Verse 36
وَإِلَىٰ مَدْيَنَ أَخَاهُمْ شُعَيْبًا فَقَالَ يَـٰقَوْمِ ٱعْبُدُوا۟ ٱللَّهَ وَٱرْجُوا۟ ٱلْيَوْمَ ٱلْـَٔاخِرَ وَلَا تَعْثَوْا۟ فِى ٱلْأَرْضِ مُفْسِدِينَ
Transliteration wa-ilā madyana akhāhum shuʿayban faqāla yāqawmi uʿ'budū l-laha wa-ir'jū l-yawma l-ākhira walā taʿthaw fī l-arḍi muf'sidīna
Yoruba A tún ránṣẹ́ sí ará ìlú Mọdyan. (A rán) arákùnrin wọn, (Ànábì) Ṣu‘aeb (níṣẹ́ sí wọn). Ó sì sọ pé: “Ẹ̀yin ìjọ mi, ẹ jọ́sìn fún Allāhu. Ẹ retí Ọjọ́ Ìkẹ́yìn, kí ẹ sì má ṣèbàjẹ́ sórí ilẹ̀.”
Verse 37
فَكَذَّبُوهُ فَأَخَذَتْهُمُ ٱلرَّجْفَةُ فَأَصْبَحُوا۟ فِى دَارِهِمْ جَـٰثِمِينَ
Transliteration fakadhabūhu fa-akhadhathumu l-rajfatu fa-aṣbaḥū fī dārihim jāthimīna
Yoruba Wọ́n pè é ní òpùrọ́. Nítorí náà, ohùn igbe líle tó mi ilẹ̀ tìtì gbá wọn mú. Wọ́n sì di ẹni tó dà lulẹ̀, tí wọ́n ti dòkú sínú ìlú wọn.
Verse 38
وَعَادًا وَثَمُودَا۟ وَقَد تَّبَيَّنَ لَكُم مِّن مَّسَـٰكِنِهِمْ ۖ وَزَيَّنَ لَهُمُ ٱلشَّيْطَـٰنُ أَعْمَـٰلَهُمْ فَصَدَّهُمْ عَنِ ٱلسَّبِيلِ وَكَانُوا۟ مُسْتَبْصِرِينَ
Transliteration waʿādan wathamūdā waqad tabayyana lakum min masākinihim wazayyana lahumu l-shayṭānu aʿmālahum faṣaddahum ʿani l-sabīli wakānū mus'tabṣirīna
Yoruba (A tún ránṣẹ́ sí àwọn) ará ‘Ād àti ará Thamūd. (Ìparun wọn) sì kúkú ti fojú hàn kedere si yín nínú àwọn ibùgbé wọn. Èṣù ṣe àwọn iṣẹ́ wọn ní ọ̀ṣọ́ fún wọn. Ó sì ṣẹ́rí wọn kúrò nínú ẹ̀sìn (Allāhu). Wọ́n sì jẹ́ olùríran (nípa ọ̀rọ̀ ayé).
Verse 39
وَقَـٰرُونَ وَفِرْعَوْنَ وَهَـٰمَـٰنَ ۖ وَلَقَدْ جَآءَهُم مُّوسَىٰ بِٱلْبَيِّنَـٰتِ فَٱسْتَكْبَرُوا۟ فِى ٱلْأَرْضِ وَمَا كَانُوا۟ سَـٰبِقِينَ
Transliteration waqārūna wafir'ʿawna wahāmāna walaqad jāahum mūsā bil-bayināti fa-is'takbarū fī l-arḍi wamā kānū sābiqīna
Yoruba (A tún ránṣẹ́ sí àwọn) Ƙọ̄rūn, Fir‘aon àti Hāmọ̄n. Dájúdájú (Ànábì) Mūsā mú àwọn ẹ̀rí tó yanjú wá bá wọn. Wọ́n sì ṣègbéraga lórí ilẹ̀. Wọn kò sì lè mórí bọ́ nínú ìyà.
Verse 40
فَكُلًّا أَخَذْنَا بِذَنۢبِهِۦ ۖ فَمِنْهُم مَّنْ أَرْسَلْنَا عَلَيْهِ حَاصِبًا وَمِنْهُم مَّنْ أَخَذَتْهُ ٱلصَّيْحَةُ وَمِنْهُم مَّنْ خَسَفْنَا بِهِ ٱلْأَرْضَ وَمِنْهُم مَّنْ أَغْرَقْنَا ۚ وَمَا كَانَ ٱللَّهُ لِيَظْلِمَهُمْ وَلَـٰكِن كَانُوٓا۟ أَنفُسَهُمْ يَظْلِمُونَ
Transliteration fakullan akhadhnā bidhanbihi famin'hum man arsalnā ʿalayhi ḥāṣiban wamin'hum man akhadhathu l-ṣayḥatu wamin'hum man khasafnā bihi l-arḍa wamin'hum man aghraqnā wamā kāna l-lahu liyaẓlimahum walākin kānū anfusahum yaẓlimūna
Yoruba A sì mú ìkọ̀ọ̀kan wọn nípa ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀. Ó wà nínú wọn, ẹni tí A fi òkúta iná ránṣẹ́ sí. Ó wà nínú wọn ẹni tí igbe líle gbá mú. Ó wà nínú wọn ẹni tí A jẹ́ kí ilẹ̀ ríri gbé e mì. Ó sì wà nínú wọn ẹni tí A tẹ̀rì sínú omi. Allāhu kò sì níí ṣàbòsí sí wọn, ṣùgbọ́n ẹ̀mí ara wọn ni wọ́n ń ṣàbòsí sí.
Verse 41
مَثَلُ ٱلَّذِينَ ٱتَّخَذُوا۟ مِن دُونِ ٱللَّهِ أَوْلِيَآءَ كَمَثَلِ ٱلْعَنكَبُوتِ ٱتَّخَذَتْ بَيْتًا ۖ وَإِنَّ أَوْهَنَ ٱلْبُيُوتِ لَبَيْتُ ٱلْعَنكَبُوتِ ۖ لَوْ كَانُوا۟ يَعْلَمُونَ
Transliteration mathalu alladhīna ittakhadhū min dūni l-lahi awliyāa kamathali l-ʿankabūti ittakhadhat baytan wa-inna awhana l-buyūti labaytu l-ʿankabūti law kānū yaʿlamūna
Yoruba Àpèjúwe àwọn tó mú àwọn (òrìṣà) ní alátìlẹ́yìn lẹ́yìn Allāhu, ó dà bí àpèjúwe aláǹtàakùn tí ó kọ́ ilé kan. Dájúdájú ilé tí ó yẹpẹrẹ jùlọ ni ilé aláǹtàakùn, tí wọ́n bá mọ̀.
Verse 42
إِنَّ ٱللَّهَ يَعْلَمُ مَا يَدْعُونَ مِن دُونِهِۦ مِن شَىْءٍ ۚ وَهُوَ ٱلْعَزِيزُ ٱلْحَكِيمُ
Transliteration inna l-laha yaʿlamu mā yadʿūna min dūnihi min shayin wahuwa l-ʿazīzu l-ḥakīmu
Yoruba Dájúdájú Allāhu mọ ohunkóhun tí wọ́n ń pè lẹ́yìn Rẹ̀. Òun sì ni Alágbára, Ọlọ́gbọ́n.
Verse 43
وَتِلْكَ ٱلْأَمْثَـٰلُ نَضْرِبُهَا لِلنَّاسِ ۖ وَمَا يَعْقِلُهَآ إِلَّا ٱلْعَـٰلِمُونَ
Transliteration watil'ka l-amthālu naḍribuhā lilnnāsi wamā yaʿqiluhā illā l-ʿālimūna
Yoruba Àwọn àkàwé wọ̀nyí, tí À ń fún àwọn ènìyàn, kò sì sí ẹni tí ó máa ṣe làákàyè nípa rẹ̀ àfi àwọn onímọ̀.
Verse 44
خَلَقَ ٱللَّهُ ٱلسَّمَـٰوَٰتِ وَٱلْأَرْضَ بِٱلْحَقِّ ۚ إِنَّ فِى ذَٰلِكَ لَـَٔايَةً لِّلْمُؤْمِنِينَ
Transliteration khalaqa l-lahu l-samāwāti wal-arḍa bil-ḥaqi inna fī dhālika laāyatan lil'mu'minīna
Yoruba Allāhu ṣẹ̀dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ pẹ̀lú òdodo. Dájúdájú àmì kan wà nínú ìyẹn fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo.
Verse 45
ٱتْلُ مَآ أُوحِىَ إِلَيْكَ مِنَ ٱلْكِتَـٰبِ وَأَقِمِ ٱلصَّلَوٰةَ ۖ إِنَّ ٱلصَّلَوٰةَ تَنْهَىٰ عَنِ ٱلْفَحْشَآءِ وَٱلْمُنكَرِ ۗ وَلَذِكْرُ ٱللَّهِ أَكْبَرُ ۗ وَٱللَّهُ يَعْلَمُ مَا تَصْنَعُونَ
Transliteration ut'lu mā ūḥiya ilayka mina l-kitābi wa-aqimi l-ṣalata inna l-ṣalata tanhā ʿani l-faḥshāi wal-munkari waladhik'ru l-lahi akbaru wal-lahu yaʿlamu mā taṣnaʿūna
Yoruba Ké ohun tí A fi ránṣẹ́ sí ọ nínú Tírà. Kí o sì kírun. Dájúdájú ìrun kíkí ń kọ ìwà ìbàjẹ́ àti aburú. Àti pé ìrántí Allāhu tóbi jùlọ. Allāhu sì mọ ohun tí ẹ̀ ń ṣe.1
Verse 46
۞ وَلَا تُجَـٰدِلُوٓا۟ أَهْلَ ٱلْكِتَـٰبِ إِلَّا بِٱلَّتِى هِىَ أَحْسَنُ إِلَّا ٱلَّذِينَ ظَلَمُوا۟ مِنْهُمْ ۖ وَقُولُوٓا۟ ءَامَنَّا بِٱلَّذِىٓ أُنزِلَ إِلَيْنَا وَأُنزِلَ إِلَيْكُمْ وَإِلَـٰهُنَا وَإِلَـٰهُكُمْ وَٰحِدٌ وَنَحْنُ لَهُۥ مُسْلِمُونَ
Transliteration walā tujādilū ahla l-kitābi illā bi-allatī hiya aḥsanu illā alladhīna ẓalamū min'hum waqūlū āmannā bi-alladhī unzila ilaynā wa-unzila ilaykum wa-ilāhunā wa-ilāhukum wāḥidun wanaḥnu lahu mus'limūna
Yoruba Ẹ má ṣe bá àwọn onítírà ṣàríyàn jiyàn àfi ní ọ̀nà tó dára jùlọ (èyí ni lílo al-Ƙur’ān àti hadīth. Ẹ má sì ṣe jà wọ́n lógun) àfi àwọn tó bá ṣàbòsí nínú wọn.Kí ẹ sì sọ pé: “A gbàgbọ́ nínú ohun tí Wọ́n sọ̀kalẹ̀ fún àwa àti ohun tí Wọ́n sọ̀kalẹ̀ fún ẹ̀yin. Ọlọ́hun wa àti Ọlọ́hun yín, (Allāhu) Ọ̀kan ṣoṣo ni. Àwa sì ni mùsùlùmí (olùjuwọ́-jusẹ̀-sílẹ̀) fún Un.”
Verse 47
وَكَذَٰلِكَ أَنزَلْنَآ إِلَيْكَ ٱلْكِتَـٰبَ ۚ فَٱلَّذِينَ ءَاتَيْنَـٰهُمُ ٱلْكِتَـٰبَ يُؤْمِنُونَ بِهِۦ ۖ وَمِنْ هَـٰٓؤُلَآءِ مَن يُؤْمِنُ بِهِۦ ۚ وَمَا يَجْحَدُ بِـَٔايَـٰتِنَآ إِلَّا ٱلْكَـٰفِرُونَ
Transliteration wakadhālika anzalnā ilayka l-kitāba fa-alladhīna ātaynāhumu l-kitāba yu'minūna bihi wamin hāulāi man yu'minu bihi wamā yajḥadu biāyātinā illā l-kāfirūna
Yoruba Báyẹn ni A ṣe sọ Tírà kalẹ̀ fún ọ. Nítorí náà, àwọn tí A fún ní Tírà, wọ́n gbà á gbọ́.Ó sì wà nínú àwọn wọ̀nyí (ìyẹn, àwọn ará Mọkkah), ẹni tó gbà á gbọ́. Kò sì sí ẹni tó ń tako àwọn āyah Wa àfi àwọn aláìgbàgbọ́.
Verse 48
وَمَا كُنتَ تَتْلُوا۟ مِن قَبْلِهِۦ مِن كِتَـٰبٍ وَلَا تَخُطُّهُۥ بِيَمِينِكَ ۖ إِذًا لَّٱرْتَابَ ٱلْمُبْطِلُونَ
Transliteration wamā kunta tatlū min qablihi min kitābin walā takhuṭṭuhu biyamīnika idhan la-ir'tāba l-mub'ṭilūna
Yoruba Ìwọ kò ké tírà kan rí ṣíwájú al-Ƙur’ān, ìwọ kò sì fi ọwọ́ ọ̀tún rẹ kọ n̄ǹkan rí. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́ nígbà náà, kí àwọn òpùrọ́ ṣeyèméjì (sí al-Ƙur’ān).
Verse 49
بَلْ هُوَ ءَايَـٰتٌۢ بَيِّنَـٰتٌ فِى صُدُورِ ٱلَّذِينَ أُوتُوا۟ ٱلْعِلْمَ ۚ وَمَا يَجْحَدُ بِـَٔايَـٰتِنَآ إِلَّا ٱلظَّـٰلِمُونَ
Transliteration bal huwa āyātun bayyinātun fī ṣudūri alladhīna ūtū l-ʿil'ma wamā yajḥadu biāyātinā illā l-ẓālimūna
Yoruba Rárá (kò rí bí wọ́n ṣe rò ó. al-Ƙur’ān), òhun ni àwọn āyah tó yanjú nínú igbá-àyà àwọn tí A fún ní ìmọ̀-ẹ̀sìn. Kò sì sí ẹni tó ń tako àwọn āyah Wa àfi àwọn alábòsí.
Verse 50
وَقَالُوا۟ لَوْلَآ أُنزِلَ عَلَيْهِ ءَايَـٰتٌ مِّن رَّبِّهِۦ ۖ قُلْ إِنَّمَا ٱلْـَٔايَـٰتُ عِندَ ٱللَّهِ وَإِنَّمَآ أَنَا۠ نَذِيرٌ مُّبِينٌ
Transliteration waqālū lawlā unzila ʿalayhi āyātun min rabbihi qul innamā l-āyātu ʿinda l-lahi wa-innamā anā nadhīrun mubīnun
Yoruba Wọ́n sì wí pé: “Nítorí kí ni Wọn kò ṣe sọ àwọn àmì (ìyanu) kan kalẹ̀ fún un láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ̀?” Sọ pé: “Allāhu nìkan ni àwọn àmì (ìyanu) wà lọ́dọ̀ Rẹ̀. Àti pé olùkìlọ̀ pọ́nńbélé ni èmi.”
Verse 51
أَوَلَمْ يَكْفِهِمْ أَنَّآ أَنزَلْنَا عَلَيْكَ ٱلْكِتَـٰبَ يُتْلَىٰ عَلَيْهِمْ ۚ إِنَّ فِى ذَٰلِكَ لَرَحْمَةً وَذِكْرَىٰ لِقَوْمٍ يُؤْمِنُونَ
Transliteration awalam yakfihim annā anzalnā ʿalayka l-kitāba yut'lā ʿalayhim inna fī dhālika laraḥmatan wadhik'rā liqawmin yu'minūna
Yoruba Ṣé kò tó fún wọn (ní àmì ìyanu) pé A sọ tírà (al-Ƙur’ān) kalẹ̀ fún ọ, tí wọ́n ń ké e fún wọn? Dájúdájú ìkẹ́ àti ìrántí wà nínú ìyẹn fún ìjọ tó gbàgbọ́.
Verse 52
قُلْ كَفَىٰ بِٱللَّهِ بَيْنِى وَبَيْنَكُمْ شَهِيدًا ۖ يَعْلَمُ مَا فِى ٱلسَّمَـٰوَٰتِ وَٱلْأَرْضِ ۗ وَٱلَّذِينَ ءَامَنُوا۟ بِٱلْبَـٰطِلِ وَكَفَرُوا۟ بِٱللَّهِ أُو۟لَـٰٓئِكَ هُمُ ٱلْخَـٰسِرُونَ
Transliteration qul kafā bil-lahi baynī wabaynakum shahīdan yaʿlamu mā fī l-samāwāti wal-arḍi wa-alladhīna āmanū bil-bāṭili wakafarū bil-lahi ulāika humu l-khāsirūna
Yoruba Sọ pé: “Allāhu tó ní Ẹlẹ́rìí láààrin èmi àti ẹ̀yin. Ó mọ ohunkóhun tó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Àwọn tó gba irọ́ (òrìṣà) gbọ́, tí wọ́n sì ṣàì gbàgbọ́ nínú Allāhu; àwọn wọ̀nyẹn, àwọn ni ẹni òfò.
Verse 53
وَيَسْتَعْجِلُونَكَ بِٱلْعَذَابِ ۚ وَلَوْلَآ أَجَلٌ مُّسَمًّى لَّجَآءَهُمُ ٱلْعَذَابُ وَلَيَأْتِيَنَّهُم بَغْتَةً وَهُمْ لَا يَشْعُرُونَ
Transliteration wayastaʿjilūnaka bil-ʿadhābi walawlā ajalun musamman lajāahumu l-ʿadhābu walayatiyannahum baghtatan wahum lā yashʿurūna
Yoruba Wọ́n sì ń kán ọ lójú nípa ìyà! Tí kò bá jẹ́ pé ó ti ní gbèdéke àkókò kan ni, ìyà náà ìbá kúkú dé bá wọn. (Ìyà) ìbá dé bá wọn ní òjijì sẹ́, tí wọn kò sì níí fura.
Verse 54
يَسْتَعْجِلُونَكَ بِٱلْعَذَابِ وَإِنَّ جَهَنَّمَ لَمُحِيطَةٌۢ بِٱلْكَـٰفِرِينَ
Transliteration yastaʿjilūnaka bil-ʿadhābi wa-inna jahannama lamuḥīṭatun bil-kāfirīna
Yoruba Wọ́n ń kán ọ lójú nípa ìyà! Dájúdájú iná Jahanamọ kúkú máa yí àwọn aláìgbàgbọ́ po.
Verse 55
يَوْمَ يَغْشَىٰهُمُ ٱلْعَذَابُ مِن فَوْقِهِمْ وَمِن تَحْتِ أَرْجُلِهِمْ وَيَقُولُ ذُوقُوا۟ مَا كُنتُمْ تَعْمَلُونَ
Transliteration yawma yaghshāhumu l-ʿadhābu min fawqihim wamin taḥti arjulihim wayaqūlu dhūqū mā kuntum taʿmalūna
Yoruba (Rántí) ọjọ́ tí ìyà yóò bò wọ́n mọ́lẹ̀ láti òkè wọn àti ìsàlẹ̀ ẹsẹ̀ wọn, (Allāhu) sì máa sọ pé: “Ẹ tọ́ (ìyà) ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́ wò.”
Verse 56
يَـٰعِبَادِىَ ٱلَّذِينَ ءَامَنُوٓا۟ إِنَّ أَرْضِى وَٰسِعَةٌ فَإِيَّـٰىَ فَٱعْبُدُونِ
Transliteration yāʿibādiya alladhīna āmanū inna arḍī wāsiʿatun fa-iyyāya fa-uʿ'budūni
Yoruba Ẹ̀yin ẹrúsìn Mi, tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, dájúdájú ilẹ̀ Mi gbòòrò. Nítorí náà, Èmi nìkan ni kí ẹ jọ́sìn fún.
Verse 57
كُلُّ نَفْسٍ ذَآئِقَةُ ٱلْمَوْتِ ۖ ثُمَّ إِلَيْنَا تُرْجَعُونَ
Transliteration kullu nafsin dhāiqatu l-mawti thumma ilaynā tur'jaʿūna
Yoruba Gbogbo ẹ̀mí l’ó máa tọ́ ikú wò. Lẹ́yìn náà, ọ̀dọ̀ Wa ni wọn yóò da yín padà sí.
Verse 58
وَٱلَّذِينَ ءَامَنُوا۟ وَعَمِلُوا۟ ٱلصَّـٰلِحَـٰتِ لَنُبَوِّئَنَّهُم مِّنَ ٱلْجَنَّةِ غُرَفًا تَجْرِى مِن تَحْتِهَا ٱلْأَنْهَـٰرُ خَـٰلِدِينَ فِيهَا ۚ نِعْمَ أَجْرُ ٱلْعَـٰمِلِينَ
Transliteration wa-alladhīna āmanū waʿamilū l-ṣāliḥāti lanubawwi-annahum mina l-janati ghurafan tajrī min taḥtihā l-anhāru khālidīna fīhā niʿ'ma ajru l-ʿāmilīna
Yoruba Àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe àwọn iṣẹ́ rere, dájúdájú A máa fi wọn sínú àwọn ilé pẹ̀tẹ́ẹ̀sì gígá kan nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra, tí odò ń ṣàn ní ìsàlẹ̀ rẹ̀. Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀. Ẹ̀san àwọn olùṣe-rere sì dára.
Verse 59
ٱلَّذِينَ صَبَرُوا۟ وَعَلَىٰ رَبِّهِمْ يَتَوَكَّلُونَ
Transliteration alladhīna ṣabarū waʿalā rabbihim yatawakkalūna
Yoruba (Àwọn ni) àwọn tó ṣe sùúrù. Olúwa wọn sì ni wọ́n ń gbáralé.
Verse 60
وَكَأَيِّن مِّن دَآبَّةٍ لَّا تَحْمِلُ رِزْقَهَا ٱللَّهُ يَرْزُقُهَا وَإِيَّاكُمْ ۚ وَهُوَ ٱلسَّمِيعُ ٱلْعَلِيمُ
Transliteration waka-ayyin min dābbatin lā taḥmilu riz'qahā l-lahu yarzuquhā wa-iyyākum wahuwa l-samīʿu l-ʿalīmu
Yoruba Mélòó mélòó nínú àwọn ẹranko tí kò lè dá bùkátà ìjẹ-ìmu rẹ̀ gbé, tí Allāhu sì ń ṣe ìjẹ-ìmu fún àwọn àti ẹ̀yin. Òun sì ni Olùgbọ́, Onímọ̀.
Verse 61
وَلَئِن سَأَلْتَهُم مَّنْ خَلَقَ ٱلسَّمَـٰوَٰتِ وَٱلْأَرْضَ وَسَخَّرَ ٱلشَّمْسَ وَٱلْقَمَرَ لَيَقُولُنَّ ٱللَّهُ ۖ فَأَنَّىٰ يُؤْفَكُونَ
Transliteration wala-in sa-altahum man khalaqa l-samāwāti wal-arḍa wasakhara l-shamsa wal-qamara layaqūlunna l-lahu fa-annā yu'fakūna
Yoruba Tí o bá bi wọ́n léèrè pé: “Ta ni Ó dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀, tí Ó sì rọ òòrùn àti òṣùpá?”, dájúdájú wọ́n á wí pé: “Allāhu ni.” Nítorí náà, báwo ni wọ́n ṣe ń ṣẹ́rí wọn kúrò níbi òdodo?
Verse 62
ٱللَّهُ يَبْسُطُ ٱلرِّزْقَ لِمَن يَشَآءُ مِنْ عِبَادِهِۦ وَيَقْدِرُ لَهُۥٓ ۚ إِنَّ ٱللَّهَ بِكُلِّ شَىْءٍ عَلِيمٌ
Transliteration al-lahu yabsuṭu l-riz'qa liman yashāu min ʿibādihi wayaqdiru lahu inna l-laha bikulli shayin ʿalīmun
Yoruba Allāhu l’Ó ń tẹ́ ọrọ̀ sílẹ̀ fún ẹni tí Ó bá fẹ́ nínú àwọn ẹrúsìn Rẹ̀. Ó sì ń díwọ̀n rẹ̀ fún ẹlòmíìràn. Dájúdájú Allāhu ni Onímọ̀ nípa gbogbo n̄ǹkan.
Verse 63
وَلَئِن سَأَلْتَهُم مَّن نَّزَّلَ مِنَ ٱلسَّمَآءِ مَآءً فَأَحْيَا بِهِ ٱلْأَرْضَ مِنۢ بَعْدِ مَوْتِهَا لَيَقُولُنَّ ٱللَّهُ ۚ قُلِ ٱلْحَمْدُ لِلَّهِ ۚ بَلْ أَكْثَرُهُمْ لَا يَعْقِلُونَ
Transliteration wala-in sa-altahum man nazzala mina l-samāi māan fa-aḥyā bihi l-arḍa min baʿdi mawtihā layaqūlunna l-lahu quli l-ḥamdu lillahi bal aktharuhum lā yaʿqilūna
Yoruba Tí o bá bi wọ́n léèrè pé: “Ta ni Ó sọ omi kalẹ̀ láti sánmọ̀, tí Ó fi ta ilẹ̀ jí lẹ́yìn tí ó ti kú?”, dájúdájú wọ́n á wí pé: “Allāhu ni.” Sọ pé: “Gbogbo ẹyìn ń jẹ́ ti Allāhu, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn ni kò ṣe làákàyè.”
Verse 64
وَمَا هَـٰذِهِ ٱلْحَيَوٰةُ ٱلدُّنْيَآ إِلَّا لَهْوٌ وَلَعِبٌ ۚ وَإِنَّ ٱلدَّارَ ٱلْـَٔاخِرَةَ لَهِىَ ٱلْحَيَوَانُ ۚ لَوْ كَانُوا۟ يَعْلَمُونَ
Transliteration wamā hādhihi l-ḥayatu l-dun'yā illā lahwun walaʿibun wa-inna l-dāra l-ākhirata lahiya l-ḥayawānu law kānū yaʿlamūna
Yoruba Kí ni ìṣẹ̀mí ayé yìí bí kò ṣe ìranù àti eré ṣíṣe. Àti pé dájúdájú Ilé Ìkẹ́yìn sì ni ìṣẹ̀mí gbére tí wọ́n bá mọ̀.
Verse 65
فَإِذَا رَكِبُوا۟ فِى ٱلْفُلْكِ دَعَوُا۟ ٱللَّهَ مُخْلِصِينَ لَهُ ٱلدِّينَ فَلَمَّا نَجَّىٰهُمْ إِلَى ٱلْبَرِّ إِذَا هُمْ يُشْرِكُونَ
Transliteration fa-idhā rakibū fī l-ful'ki daʿawū l-laha mukh'liṣīna lahu l-dīna falammā najjāhum ilā l-bari idhā hum yush'rikūna
Yoruba Nígbà tí wọ́n bá gun ọkọ̀ ojú-omi, wọ́n máa pe Allāhu lẹ́ni tí yóò máa fi àfọ̀mọ́-ọkàn (àníyàn mímọ́) ṣe ẹ̀sìn fún Un.Àmọ́ nígbà tí Ó bá gbà wọ́n là sí orí ilẹ̀, nígbà náà ni wọn yóò máa ṣẹbọ
Verse 66
لِيَكْفُرُوا۟ بِمَآ ءَاتَيْنَـٰهُمْ وَلِيَتَمَتَّعُوا۟ ۖ فَسَوْفَ يَعْلَمُونَ
Transliteration liyakfurū bimā ātaynāhum waliyatamattaʿū fasawfa yaʿlamūna
Yoruba nítorí kí wọ́n lè ṣàì moore sí n̄ǹkan tí A fún wọn àti nítorí kí wọ́n lè jayékáyé. Nítorí náà, láìpẹ́ wọ́n máa mọ̀.
Verse 67
أَوَلَمْ يَرَوْا۟ أَنَّا جَعَلْنَا حَرَمًا ءَامِنًا وَيُتَخَطَّفُ ٱلنَّاسُ مِنْ حَوْلِهِمْ ۚ أَفَبِٱلْبَـٰطِلِ يُؤْمِنُونَ وَبِنِعْمَةِ ٱللَّهِ يَكْفُرُونَ
Transliteration awalam yaraw annā jaʿalnā ḥaraman āminan wayutakhaṭṭafu l-nāsu min ḥawlihim afabil-bāṭili yu'minūna wabiniʿ'mati l-lahi yakfurūna
Yoruba Ṣé wọn kò rí i pé dájúdájú Àwa ṣe Haram (Mọkkah) ni àyè ìfàyàbalẹ̀, tí wọ́n sì ń jí àwọn ènìyàn gbé lọ ní àyíká wọn? Ṣé irọ́ (òrìṣà) ni wọn yóò gbàgbọ́, tí wọn yó sì ṣàì moore sí ìdẹ̀ra Allāhu?
Verse 68
وَمَنْ أَظْلَمُ مِمَّنِ ٱفْتَرَىٰ عَلَى ٱللَّهِ كَذِبًا أَوْ كَذَّبَ بِٱلْحَقِّ لَمَّا جَآءَهُۥٓ ۚ أَلَيْسَ فِى جَهَنَّمَ مَثْوًى لِّلْكَـٰفِرِينَ
Transliteration waman aẓlamu mimmani if'tarā ʿalā l-lahi kadhiban aw kadhaba bil-ḥaqi lammā jāahu alaysa fī jahannama mathwan lil'kāfirīna
Yoruba Ta ló ṣàbòsí ju ẹni tó dá àdápa irọ́ mọ́ Allāhu, tàbí tó pe òdodo ní irọ́ nígbà tí ó dé bá a? Ṣé inú iná Jahanamọ kọ́ ni ibùgbé fún àwọn aláìgbàgbọ́ ni?
Verse 69
وَٱلَّذِينَ جَـٰهَدُوا۟ فِينَا لَنَهْدِيَنَّهُمْ سُبُلَنَا ۚ وَإِنَّ ٱللَّهَ لَمَعَ ٱلْمُحْسِنِينَ
Transliteration wa-alladhīna jāhadū fīnā lanahdiyannahum subulanā wa-inna l-laha lamaʿa l-muḥ'sinīna
Yoruba Àwọn tó gbìyànjú nípa Wa, dájúdájú A máa fi wọ́n mọ àwọn ọ̀nà Wa. Àti pé dájúdájú Allāhu wà pẹ̀lú àwọn olúṣe-rere.
Read Surah Al-'Ankabut in another language
- English (word by word)
- Albanian
- Amazigh
- Amharic
- Assamese
- Azerbaijani
- Bambara
- Bangla
- Bosnian
- Bulgarian
- Chechen
- Chinese
- Czech
- Dari
- Dhivehi
- Dutch
- Finnish
- French
- German
- Gujarati
- Hausa
- Hebrew
- Hindi
- Indonesian
- Italian
- Japanese
- Kannada
- Kazakh
- Khmer
- Kinyarwanda
- Korean
- Kurdish
- Luganda
- Malay
- Malayalam
- Maranao
- Marathi
- Nepali
- Norwegian
- Oromo
- Pashto
- Persian
- Polish
- Portuguese
- Romanian
- Russian
- Sindhi
- Sinhala
- Somali
- Spanish
- Swahili
- Swedish
- Tagalog
- Tajik
- Tamil
- Tatar
- Telugu
- Thai
- Turkish
- Ukrainian
- Urdu
- Uyghur
- Uzbek
- Vietnamese
- Yao
All 114 surahs in Yoruba: the Qur’an in Yoruba.
Yoruba translation: Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni, from Quran.com. Transliteration: Quran.com. Recitation: Mishary Alafasy, from EveryAyah.com. MyDugsi is a learning aid, not a replacement for a qualified teacher.