MyDugsiStart learning

Surah Al-Ahqaf in Yoruba: translation and audio

Surah 46 · الأحقاف · The Wind-Curved Sandhills · 35 verses

Surah Al-Ahqaf verse by verse: the Arabic with a recitation you can repeat, the transliteration, and the Yoruba translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni. For the meaning of every word, see Surah Al-Ahqaf word by word in English.

Verse 1

حمٓ

Transliteration hha-meem

Yoruba Hā mīm. (Allāhu ló mọ ohun tí Ó gbàlérò pẹ̀lú àwọn háràfí náà.)1

Verse 2

تَنزِيلُ ٱلْكِتَـٰبِ مِنَ ٱللَّهِ ٱلْعَزِيزِ ٱلْحَكِيمِ

Transliteration tanzīlu l-kitābi mina l-lahi l-ʿazīzi l-ḥakīmi

Yoruba Tírà náà sọ̀kalẹ̀ díẹ̀ díẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Allāhu, Alágbára, Ọlọ́gbọ́n.

Verse 3

مَا خَلَقْنَا ٱلسَّمَـٰوَٰتِ وَٱلْأَرْضَ وَمَا بَيْنَهُمَآ إِلَّا بِٱلْحَقِّ وَأَجَلٍ مُّسَمًّى ۚ وَٱلَّذِينَ كَفَرُوا۟ عَمَّآ أُنذِرُوا۟ مُعْرِضُونَ

Transliteration mā khalaqnā l-samāwāti wal-arḍa wamā baynahumā illā bil-ḥaqi wa-ajalin musamman wa-alladhīna kafarū ʿammā undhirū muʿ'riḍūna

Yoruba A kò ṣẹ̀dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀, àti ohunkóhun tó wà láààrin méjèèjì bí kò ṣe pẹ̀lú òdodo àti fún gbèdéke àkókò kan. Àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ yó sì máa gbúnrí kúrò níbi ohun tí A fi ṣèkìlọ̀ fún wọn.

Verse 4

قُلْ أَرَءَيْتُم مَّا تَدْعُونَ مِن دُونِ ٱللَّهِ أَرُونِى مَاذَا خَلَقُوا۟ مِنَ ٱلْأَرْضِ أَمْ لَهُمْ شِرْكٌ فِى ٱلسَّمَـٰوَٰتِ ۖ ٱئْتُونِى بِكِتَـٰبٍ مِّن قَبْلِ هَـٰذَآ أَوْ أَثَـٰرَةٍ مِّنْ عِلْمٍ إِن كُنتُمْ صَـٰدِقِينَ

Transliteration qul ara-aytum mā tadʿūna min dūni l-lahi arūnī mādhā khalaqū mina l-arḍi am lahum shir'kun fī l-samāwāti i'tūnī bikitābin min qabli hādhā aw athāratin min ʿil'min in kuntum ṣādiqīna

Yoruba Sọ pé: “Ẹ sọ fún mi nípa n̄ǹkan tí ẹ̀ ń pè lẹ́yìn Allāhu; ẹ fi wọ́n hàn mí ná, kí ni wọ́n ṣẹ̀dá nínú (ohun tó wà lórí) ilẹ̀. Tàbí wọ́n ní ìpín kan (pẹ̀lú Allāhu) nínú (ìṣẹ̀dá) àwọn sánmọ̀? Ẹ mú Tírà kan wá fún mi tó ṣíwájú (al-Ƙur’ān) yìí tàbí orípa kan nínú ìmọ̀ tí ẹ bá jẹ́ olódodo.”

Verse 5

وَمَنْ أَضَلُّ مِمَّن يَدْعُوا۟ مِن دُونِ ٱللَّهِ مَن لَّا يَسْتَجِيبُ لَهُۥٓ إِلَىٰ يَوْمِ ٱلْقِيَـٰمَةِ وَهُمْ عَن دُعَآئِهِمْ غَـٰفِلُونَ

Transliteration waman aḍallu mimman yadʿū min dūni l-lahi man lā yastajību lahu ilā yawmi l-qiyāmati wahum ʿan duʿāihim ghāfilūna

Yoruba Ta l’ó sì ṣìnà ju ẹni tí ó ń pè lẹ́yìn Allāhu, ẹni tí kò lè jẹ́ ìpè rẹ̀ títí di Ọjọ́ Àjíǹde! Àti pé wọn kò ní òye sí pípè tí wọ́n ń pè wọ́n.1

Verse 6

وَإِذَا حُشِرَ ٱلنَّاسُ كَانُوا۟ لَهُمْ أَعْدَآءً وَكَانُوا۟ بِعِبَادَتِهِمْ كَـٰفِرِينَ

Transliteration wa-idhā ḥushira l-nāsu kānū lahum aʿdāan wakānū biʿibādatihim kāfirīna

Yoruba Nígbà tí A bá sì kó àwọn ènìyàn jọ (fún Àjíǹde), àwọn òrìṣà yóò di ọ̀tá fún àwọn abọ̀rìṣà. Wọ́n sì máa tako ìjọ́sìn tí wọ́n ṣe fún wọn.

Verse 7

وَإِذَا تُتْلَىٰ عَلَيْهِمْ ءَايَـٰتُنَا بَيِّنَـٰتٍ قَالَ ٱلَّذِينَ كَفَرُوا۟ لِلْحَقِّ لَمَّا جَآءَهُمْ هَـٰذَا سِحْرٌ مُّبِينٌ

Transliteration wa-idhā tut'lā ʿalayhim āyātunā bayyinātin qāla alladhīna kafarū lil'ḥaqqi lammā jāahum hādhā siḥ'run mubīnun

Yoruba Nígbà tí wọ́n bá ń ké áwọn āyah Wa tó yanjú fún wọn, àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ yó sì máa sọ ìsọkúsọ sí òdodo nígbà tí ó dé bá wọn pé: “Èyí ni idán pọ́nńbélé.”

Verse 8

أَمْ يَقُولُونَ ٱفْتَرَىٰهُ ۖ قُلْ إِنِ ٱفْتَرَيْتُهُۥ فَلَا تَمْلِكُونَ لِى مِنَ ٱللَّهِ شَيْـًٔا ۖ هُوَ أَعْلَمُ بِمَا تُفِيضُونَ فِيهِ ۖ كَفَىٰ بِهِۦ شَهِيدًۢا بَيْنِى وَبَيْنَكُمْ ۖ وَهُوَ ٱلْغَفُورُ ٱلرَّحِيمُ

Transliteration am yaqūlūna if'tarāhu qul ini if'taraytuhu falā tamlikūna lī mina l-lahi shayan huwa aʿlamu bimā tufīḍūna fīhi kafā bihi shahīdan baynī wabaynakum wahuwa l-ghafūru l-raḥīmu

Yoruba Tàbí wọ́n ń wí pé: “Ó dá (al-Ƙur’ān) hun fúnra rẹ̀ ni.” Sọ pé: “Tí mo bá hun ún fúnra mi, ẹ kò ní ìkápá kiní kan fún mi ní ọ̀dọ̀ Allāhu (níbi ìyà Rẹ̀). Òun ni Onímọ̀-jùlọ nípa ìsọkúsọ tí ẹ̀ ń sọ nípa rẹ̀. Ó (sì) tó ní Ẹlẹ́rìí láààrin èmi àti ẹ̀yin. Òun ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.”

Verse 9

قُلْ مَا كُنتُ بِدْعًا مِّنَ ٱلرُّسُلِ وَمَآ أَدْرِى مَا يُفْعَلُ بِى وَلَا بِكُمْ ۖ إِنْ أَتَّبِعُ إِلَّا مَا يُوحَىٰٓ إِلَىَّ وَمَآ أَنَا۠ إِلَّا نَذِيرٌ مُّبِينٌ

Transliteration qul mā kuntu bid'ʿan mina l-rusuli wamā adrī mā yuf'ʿalu bī walā bikum in attabiʿu illā mā yūḥā ilayya wamā anā illā nadhīrun mubīnun

Yoruba Sọ pé: “Èmi kì í ṣe àkọ́kọ́ nínú àwọn Òjíṣẹ́. Èmi kò sì mọ n̄ǹkan tí wọ́n máa ṣe fún èmi àti ẹ̀yin.Èmi kò tẹ̀lé kiní kan àyàfi ohun tí Wọ́n fi ránṣẹ́ sí mi ní ìmísí. Èmi kò sì jẹ́ kiní kan bí kò ṣe olùkìlọ̀ pọ́nńbélé.”

Verse 10

قُلْ أَرَءَيْتُمْ إِن كَانَ مِنْ عِندِ ٱللَّهِ وَكَفَرْتُم بِهِۦ وَشَهِدَ شَاهِدٌ مِّنۢ بَنِىٓ إِسْرَٰٓءِيلَ عَلَىٰ مِثْلِهِۦ فَـَٔامَنَ وَٱسْتَكْبَرْتُمْ ۖ إِنَّ ٱللَّهَ لَا يَهْدِى ٱلْقَوْمَ ٱلظَّـٰلِمِينَ

Transliteration qul ara-aytum in kāna min ʿindi l-lahi wakafartum bihi washahida shāhidun min banī is'rāīla ʿalā mith'lihi faāmana wa-is'takbartum inna l-laha lā yahdī l-qawma l-ẓālimīna

Yoruba Sọ pé: “Ẹ sọ fún mi, tí ó bá jẹ́ pé láti ọ̀dọ̀ Allāhu ni (al-Ƙur’ān) ti wá, tí ẹ sì ṣàì gbàgbọ́ nínú rẹ̀, tí ẹlẹ́rìí kan nínú àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl sì jẹ́rìí lórí irú rẹ̀, tí ó sì gbà á gbọ́, (àmọ́) tí ẹ̀yin ṣègbéraga sí i, (ṣé ẹ ò ti ṣàbòsí báyẹn bí?). Dájúdájú Allāhu kò níí fi ọ̀nà mọ ìjọ alábòsí.

Verse 11

وَقَالَ ٱلَّذِينَ كَفَرُوا۟ لِلَّذِينَ ءَامَنُوا۟ لَوْ كَانَ خَيْرًا مَّا سَبَقُونَآ إِلَيْهِ ۚ وَإِذْ لَمْ يَهْتَدُوا۟ بِهِۦ فَسَيَقُولُونَ هَـٰذَآ إِفْكٌ قَدِيمٌ

Transliteration waqāla alladhīna kafarū lilladhīna āmanū law kāna khayran mā sabaqūnā ilayhi wa-idh lam yahtadū bihi fasayaqūlūna hādhā if'kun qadīmun

Yoruba Àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ wí fún àwọn tó gbàgbọ́ pé: “Tí ó bá jẹ́ pé al-Ƙur’ān jẹ́ oore ni, wọn kò níí ṣíwájú wa débẹ̀.” Nígbà tí àwọn ọ̀ṣẹbọ kò ti tẹ̀lé ìmọ̀nà rẹ̀, ni wọ́n ń wí pé: “Irọ́ ijọ́un ni èyí.”

Verse 12

وَمِن قَبْلِهِۦ كِتَـٰبُ مُوسَىٰٓ إِمَامًا وَرَحْمَةً ۚ وَهَـٰذَا كِتَـٰبٌ مُّصَدِّقٌ لِّسَانًا عَرَبِيًّا لِّيُنذِرَ ٱلَّذِينَ ظَلَمُوا۟ وَبُشْرَىٰ لِلْمُحْسِنِينَ

Transliteration wamin qablihi kitābu mūsā imāman waraḥmatan wahādhā kitābun muṣaddiqun lisānan ʿarabiyyan liyundhira alladhīna ẓalamū wabush'rā lil'muḥ'sinīna

Yoruba Tírà (Ànábì) Mūsā sì ti wá ṣíwájú rẹ̀, tí ó jẹ́ tírà tí wọ́n ń tẹ̀lé, ó sì jẹ́ ìkẹ́ (fún wọn. Al-Ƙur’ān) yìí tún ni Tírà kan tó ń jẹ́rìí sí òdodo ní èdè Lárúbáwá nítorí kí ó lè ṣèkìlọ̀ fún àwọn tó ṣàbòsí, (ó sì jẹ́) ìró ìdùnnú fún àwọn olùṣe-rere.

Verse 13

إِنَّ ٱلَّذِينَ قَالُوا۟ رَبُّنَا ٱللَّهُ ثُمَّ ٱسْتَقَـٰمُوا۟ فَلَا خَوْفٌ عَلَيْهِمْ وَلَا هُمْ يَحْزَنُونَ

Transliteration inna alladhīna qālū rabbunā l-lahu thumma is'taqāmū falā khawfun ʿalayhim walā hum yaḥzanūna

Yoruba Dájúdájú àwọn tó sọ pé: “Allāhu ni Olúwa wa”, lẹ́yìn náà, tí wọ́n dúró ṣinṣin nínú ẹ̀sìn, kò níí sí ìpáyà fún wọn. Wọn kò sì níí banújẹ́.

Verse 14

أُو۟لَـٰٓئِكَ أَصْحَـٰبُ ٱلْجَنَّةِ خَـٰلِدِينَ فِيهَا جَزَآءًۢ بِمَا كَانُوا۟ يَعْمَلُونَ

Transliteration ulāika aṣḥābu l-janati khālidīna fīhā jazāan bimā kānū yaʿmalūna

Yoruba Àwọn wọ̀nyẹn ni èrò inú Ọgbà Ìdẹ̀ra. Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀. (Ó jẹ́) ẹ̀san nítorí ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́.

Verse 15

وَوَصَّيْنَا ٱلْإِنسَـٰنَ بِوَٰلِدَيْهِ إِحْسَـٰنًا ۖ حَمَلَتْهُ أُمُّهُۥ كُرْهًا وَوَضَعَتْهُ كُرْهًا ۖ وَحَمْلُهُۥ وَفِصَـٰلُهُۥ ثَلَـٰثُونَ شَهْرًا ۚ حَتَّىٰٓ إِذَا بَلَغَ أَشُدَّهُۥ وَبَلَغَ أَرْبَعِينَ سَنَةً قَالَ رَبِّ أَوْزِعْنِىٓ أَنْ أَشْكُرَ نِعْمَتَكَ ٱلَّتِىٓ أَنْعَمْتَ عَلَىَّ وَعَلَىٰ وَٰلِدَىَّ وَأَنْ أَعْمَلَ صَـٰلِحًا تَرْضَىٰهُ وَأَصْلِحْ لِى فِى ذُرِّيَّتِىٓ ۖ إِنِّى تُبْتُ إِلَيْكَ وَإِنِّى مِنَ ٱلْمُسْلِمِينَ

Transliteration wawaṣṣaynā l-insāna biwālidayhi iḥ'sānan ḥamalathu ummuhu kur'han wawaḍaʿathu kur'han waḥamluhu wafiṣāluhu thalāthūna shahran ḥattā idhā balagha ashuddahu wabalagha arbaʿīna sanatan qāla rabbi awziʿ'nī an ashkura niʿ'mataka allatī anʿamta ʿalayya waʿalā wālidayya wa-an aʿmala ṣāliḥan tarḍāhu wa-aṣliḥ lī fī dhurriyyatī innī tub'tu ilayka wa-innī mina l-mus'limīna

Yoruba A pa á ní àsẹ fún ènìyàn pé kí ó máa ṣe dáadáa sí àwọn òbí rẹ̀ méjèèjì. Ìyá rẹ̀ ní oyún rẹ̀ pẹ̀lú wàhálà. Ó sì bí i pẹ̀lú wàhálà. Oyún rẹ̀ àti gbígba ọmú lẹ́nu rẹ̀ jẹ́ ọgbọ̀n oṣù. (Ó sì ń tọ́ ọ) títí ó fi dàgbà dáadáa, tí ó fi di ọmọ ogójì ọdún, ó sì sọ pé: “Olúwa mi, fi mọ̀ mí kí n̄g máa dúpẹ́ ìdẹ̀ra Rẹ, èyí tí Ó fi ṣe ìdẹ̀ra fún mi àti fún àwọn òbí mi méjèèjì, kí n̄g sì máa ṣe iṣẹ́ rere, èyí tí O yọ́nú sí. Kí O sì ṣe rere fún mi lórí àwọn àrọ́mọdọ́mọ mi. Dájúdájú èmi ti ronú pìwàdà sí ọ̀dọ̀ Rẹ. Dájúdájú èmi sì wà nínú àwọn mùsùlùmí.”

Verse 16

أُو۟لَـٰٓئِكَ ٱلَّذِينَ نَتَقَبَّلُ عَنْهُمْ أَحْسَنَ مَا عَمِلُوا۟ وَنَتَجَاوَزُ عَن سَيِّـَٔاتِهِمْ فِىٓ أَصْحَـٰبِ ٱلْجَنَّةِ ۖ وَعْدَ ٱلصِّدْقِ ٱلَّذِى كَانُوا۟ يُوعَدُونَ

Transliteration ulāika alladhīna nataqabbalu ʿanhum aḥsana mā ʿamilū wanatajāwazu ʿan sayyiātihim fī aṣḥābi l-janati waʿda l-ṣid'qi alladhī kānū yūʿadūna

Yoruba Àwọn wọ̀nyẹn ni àwọn tí A máa gba iṣẹ́ rere tí wọ́n ṣe níṣẹ́, A sì máa ṣe àmójúkúrò níbi àwọn aburú iṣẹ́ wọn; wọ́n máa wà nínú àwọn èrò inú Ọgbà Ìdẹ̀ra. (Ó jẹ́) àdéhùn òdodo tí À ń ṣe ní àdéhùn fún wọn.

Verse 17

وَٱلَّذِى قَالَ لِوَٰلِدَيْهِ أُفٍّ لَّكُمَآ أَتَعِدَانِنِىٓ أَنْ أُخْرَجَ وَقَدْ خَلَتِ ٱلْقُرُونُ مِن قَبْلِى وَهُمَا يَسْتَغِيثَانِ ٱللَّهَ وَيْلَكَ ءَامِنْ إِنَّ وَعْدَ ٱللَّهِ حَقٌّ فَيَقُولُ مَا هَـٰذَآ إِلَّآ أَسَـٰطِيرُ ٱلْأَوَّلِينَ

Transliteration wa-alladhī qāla liwālidayhi uffin lakumā ataʿidāninī an ukh'raja waqad khalati l-qurūnu min qablī wahumā yastaghīthāni l-laha waylaka āmin inna waʿda l-lahi ḥaqqun fayaqūlu mā hādhā illā asāṭīru l-awalīna

Yoruba Ẹni tí ó sọ fún àwọn òbí rẹ̀ méjèèjì pé: “Ṣíọ̀ ẹ̀yin méjèèjì! Ṣé ẹ̀yin yóò máa ṣèlérí fún mi pé Wọn yóò mú mi jáde (láàyè láti inú sàréè), ṣebí àwọn ìran kan ti ré kọjá lọ ṣíwájú mi (tí Wọn kò tí ì mú wọn jáde láti inú sàréè wọn).” Àwọn (òbí rẹ̀) méjèèjì sì ń tọrọ ìgbàlà ní ọ̀dọ̀ Allāhu (fún ọmọ yìí. Wọ́n sì sọ pé): “Ègbé ni fún ọ! (O jẹ́) gbàgbọ́ ní òdodo. Dájúdájú àdéhùn Allāhu ni òdodo.” (Ọ̀mọ̀ náà sì) wí pé: “Èyí kò jẹ́ kiní kan bí kò ṣe àkọsílẹ̀ àlọ́ àwọn ẹni àkọ́kọ́.”

Verse 18

أُو۟لَـٰٓئِكَ ٱلَّذِينَ حَقَّ عَلَيْهِمُ ٱلْقَوْلُ فِىٓ أُمَمٍ قَدْ خَلَتْ مِن قَبْلِهِم مِّنَ ٱلْجِنِّ وَٱلْإِنسِ ۖ إِنَّهُمْ كَانُوا۟ خَـٰسِرِينَ

Transliteration ulāika alladhīna ḥaqqa ʿalayhimu l-qawlu fī umamin qad khalat min qablihim mina l-jini wal-insi innahum kānū khāsirīna

Yoruba Àwọn (aláìgbàgbọ́) wọ̀nyẹn ni àwọn tí ọ̀rọ̀ náà ti kò lé lórí nínú àwọn ìjọ kan tí ó ti ré kọjá ṣíwájú wọn nínú àwọn àlùjànnú àti ènìyàn. Dájúdájú wọ́n jẹ́ ẹni òfò.

Verse 19

وَلِكُلٍّ دَرَجَـٰتٌ مِّمَّا عَمِلُوا۟ ۖ وَلِيُوَفِّيَهُمْ أَعْمَـٰلَهُمْ وَهُمْ لَا يُظْلَمُونَ

Transliteration walikullin darajātun mimmā ʿamilū waliyuwaffiyahum aʿmālahum wahum lā yuẓ'lamūna

Yoruba Àwọn ipò yóò wà fún ẹnì kọ̀ọ̀kan nípa iṣẹ́ tí wọ́n ṣe níṣẹ́. Àti pé (èyí rí bẹ́ẹ̀) nítorí kí (Allāhu) lè san wọ́n ní ẹ̀san iṣẹ́ wọn ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́. Àwa kò sì níí ṣàbòsí sí wọn.

Verse 20

وَيَوْمَ يُعْرَضُ ٱلَّذِينَ كَفَرُوا۟ عَلَى ٱلنَّارِ أَذْهَبْتُمْ طَيِّبَـٰتِكُمْ فِى حَيَاتِكُمُ ٱلدُّنْيَا وَٱسْتَمْتَعْتُم بِهَا فَٱلْيَوْمَ تُجْزَوْنَ عَذَابَ ٱلْهُونِ بِمَا كُنتُمْ تَسْتَكْبِرُونَ فِى ٱلْأَرْضِ بِغَيْرِ ٱلْحَقِّ وَبِمَا كُنتُمْ تَفْسُقُونَ

Transliteration wayawma yuʿ'raḍu alladhīna kafarū ʿalā l-nāri adhhabtum ṭayyibātikum fī ḥayātikumu l-dun'yā wa-is'tamtaʿtum bihā fal-yawma tuj'zawna ʿadhāba l-hūni bimā kuntum tastakbirūna fī l-arḍi bighayri l-ḥaqi wabimā kuntum tafsuqūna

Yoruba Ní ọjọ́ tí wọ́n máa darí àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ kọ Iná, (wọ́n máa sọ fún wọn pé:) “Ẹ ti lo ìgbádùn yín tán nínú ìṣẹ̀mí ayé? Ẹ sì ti jẹ ìgbádùn ayé? Nítorí náà, ní òní, wọ́n máa san yín ní ẹ̀san àbùkù ìyà nítorí pé ẹ̀ ń ṣègbéraga ní orí ilẹ̀ láì lẹ́tọ̀ọ́ àti nítorí pé ẹ̀ ń ṣèbàjẹ́.”

Verse 21

۞ وَٱذْكُرْ أَخَا عَادٍ إِذْ أَنذَرَ قَوْمَهُۥ بِٱلْأَحْقَافِ وَقَدْ خَلَتِ ٱلنُّذُرُ مِنۢ بَيْنِ يَدَيْهِ وَمِنْ خَلْفِهِۦٓ أَلَّا تَعْبُدُوٓا۟ إِلَّا ٱللَّهَ إِنِّىٓ أَخَافُ عَلَيْكُمْ عَذَابَ يَوْمٍ عَظِيمٍ

Transliteration wa-udh'kur akhā ʿādin idh andhara qawmahu bil-aḥqāfi waqad khalati l-nudhuru min bayni yadayhi wamin khalfihi allā taʿbudū illā l-laha innī akhāfu ʿalaykum ʿadhāba yawmin ʿaẓīmin

Yoruba Ṣèrántí arákùnrin (ìjọ) ‘Ād. Nígbà tí ó ṣèkìlọ̀ fún àwọn ènìyàn rẹ̀ tó ń gbé nínú yanrìn tí atẹ́gùn kójọ bí òkè. Àwọn olùkìlọ̀ sì ti ré kọjá ṣíwájú rẹ̀ àti lẹ́yìn rẹ̀. (Ó sì sọ pé:) “Ẹ̀yin kò gbọdọ̀ jọ́sìn fún kiní kan àyàfi Allāhu. Dájúdájú èmi ń páyà ìyà ọjọ́ ńlá kan fún yín.”

Verse 22

قَالُوٓا۟ أَجِئْتَنَا لِتَأْفِكَنَا عَنْ ءَالِهَتِنَا فَأْتِنَا بِمَا تَعِدُنَآ إِن كُنتَ مِنَ ٱلصَّـٰدِقِينَ

Transliteration qālū aji'tanā litafikanā ʿan ālihatinā fatinā bimā taʿidunā in kunta mina l-ṣādiqīna

Yoruba Wọ́n wí pé: “Ṣé ìwọ wá bá wa láti ṣẹ́ wa lórí kúrò níbi àwọn òrìṣà wa ni? Mú ohun tí ò ń ṣe ìlérí rẹ̀ fún wa wá tí ìwọ bá wà nínú àwọn olódodo.”

Verse 23

قَالَ إِنَّمَا ٱلْعِلْمُ عِندَ ٱللَّهِ وَأُبَلِّغُكُم مَّآ أُرْسِلْتُ بِهِۦ وَلَـٰكِنِّىٓ أَرَىٰكُمْ قَوْمًا تَجْهَلُونَ

Transliteration qāla innamā l-ʿil'mu ʿinda l-lahi wa-uballighukum mā ur'sil'tu bihi walākinnī arākum qawman tajhalūna

Yoruba Ó sọ pé: “Ìmọ̀ (nípa rẹ̀) wà ní ọ̀dọ̀ Allāhu nìkan ṣoṣo. Èmi yó sì jẹ́ ohun tí Wọ́n fi rán mi níṣẹ́ dé òpin fún yín, ṣùgbọ́n èmi ń ri ẹ̀yin ní ìjọ aláìmọ̀kan.”

Verse 24

فَلَمَّا رَأَوْهُ عَارِضًا مُّسْتَقْبِلَ أَوْدِيَتِهِمْ قَالُوا۟ هَـٰذَا عَارِضٌ مُّمْطِرُنَا ۚ بَلْ هُوَ مَا ٱسْتَعْجَلْتُم بِهِۦ ۖ رِيحٌ فِيهَا عَذَابٌ أَلِيمٌ

Transliteration falammā ra-awhu ʿāriḍan mus'taqbila awdiyatihim qālū hādhā ʿāriḍun mum'ṭirunā bal huwa mā is'taʿjaltum bihi rīḥun fīhā ʿadhābun alīmun

Yoruba Nígbà tí wọ́n rí ìyà náà ní ẹ̀ṣújò rẹgẹdẹ, tó ń wọ́ bọ̀ wá sínú àwọn kòtò ìlú wọn, wọ́n wí pé: “Èyí ni ẹ̀ṣújò rẹgẹdẹ, tí ó máa rọ̀jò fún wa.” Kò sì rí bẹ́ẹ̀, ohun tí ẹ̀ ń wá pẹ̀lú ìkánjú ni. Atẹ́gùn tí ìyà ẹlẹ́ta-eléro wà nínú rẹ̀ ni.

Verse 25

تُدَمِّرُ كُلَّ شَىْءٍۭ بِأَمْرِ رَبِّهَا فَأَصْبَحُوا۟ لَا يُرَىٰٓ إِلَّا مَسَـٰكِنُهُمْ ۚ كَذَٰلِكَ نَجْزِى ٱلْقَوْمَ ٱلْمُجْرِمِينَ

Transliteration tudammiru kulla shayin bi-amri rabbihā fa-aṣbaḥū lā yurā illā masākinuhum kadhālika najzī l-qawma l-muj'rimīna

Yoruba Ó ń pa gbogbo n̄ǹkan rẹ́ (ìyẹn nínú ìlú wọn) pẹ̀lú àṣẹ Olúwa rẹ̀. Nígbà náà, wọ́n di ẹni tí wọn kò rí mọ́ àfi àwọn ibùgbé wọn. Báyẹn ni A ṣe ń san ìjọ ẹlẹ́ṣẹ̀ ní ẹ̀san.

Verse 26

وَلَقَدْ مَكَّنَّـٰهُمْ فِيمَآ إِن مَّكَّنَّـٰكُمْ فِيهِ وَجَعَلْنَا لَهُمْ سَمْعًا وَأَبْصَـٰرًا وَأَفْـِٔدَةً فَمَآ أَغْنَىٰ عَنْهُمْ سَمْعُهُمْ وَلَآ أَبْصَـٰرُهُمْ وَلَآ أَفْـِٔدَتُهُم مِّن شَىْءٍ إِذْ كَانُوا۟ يَجْحَدُونَ بِـَٔايَـٰتِ ٱللَّهِ وَحَاقَ بِهِم مَّا كَانُوا۟ بِهِۦ يَسْتَهْزِءُونَ

Transliteration walaqad makkannāhum fīmā in makkannākum fīhi wajaʿalnā lahum samʿan wa-abṣāran wa-afidatan famā aghnā ʿanhum samʿuhum walā abṣāruhum walā afidatuhum min shayin idh kānū yajḥadūna biāyāti l-lahi waḥāqa bihim mā kānū bihi yastahziūna

Yoruba A kúkú fún wọn ní ipò tí A kò fún ẹ̀yin. A sì fún wọn ní ìgbọ́rọ̀, àwọn ìríran àti àwọn ọkàn. Àmọ́ ìgbọ́rọ̀ wọn àti àwọn ìríran wọn pẹ̀lú àwọn ọkàn wọn kò rọ̀ wọ́n lọ́rọ̀ kan kan níbi ìyà nítorí pé wọ́n ń ṣe àtakò sí àwọn āyah Allāhu. Àti pé ohun tí wọ́n ń fi ṣe yẹ̀yẹ́ sì dìyà tó yí wọn po.

Verse 27

وَلَقَدْ أَهْلَكْنَا مَا حَوْلَكُم مِّنَ ٱلْقُرَىٰ وَصَرَّفْنَا ٱلْـَٔايَـٰتِ لَعَلَّهُمْ يَرْجِعُونَ

Transliteration walaqad ahlaknā mā ḥawlakum mina l-qurā waṣarrafnā l-āyāti laʿallahum yarjiʿūna

Yoruba Àwa kúkú ti pa rẹ́ nínú àwọn ìlú tí ó wà ní àyíká yín. Àwa sì ti ṣàlàyé àwọn āyah náà ní oríṣiríṣi ọ̀nà nítorí kí wọ́n lè ṣẹ́rí padà (síbi òdodo).

Verse 28

فَلَوْلَا نَصَرَهُمُ ٱلَّذِينَ ٱتَّخَذُوا۟ مِن دُونِ ٱللَّهِ قُرْبَانًا ءَالِهَةًۢ ۖ بَلْ ضَلُّوا۟ عَنْهُمْ ۚ وَذَٰلِكَ إِفْكُهُمْ وَمَا كَانُوا۟ يَفْتَرُونَ

Transliteration falawlā naṣarahumu alladhīna ittakhadhū min dūni l-lahi qur'bānan ālihatan bal ḍallū ʿanhum wadhālika if'kuhum wamā kānū yaftarūna

Yoruba Àwọn ọlọ́hun tí wọ́n sọ di ohun tí ó máa mú wọn súnmọ́ (ìgbàlà) lẹ́yìn Allāhu kò ṣe ràn wọ́n lọ́wọ́ mọ́? Rárá (kò lè sí àrànṣe fún wọn)! Wọ́n ti di ofò mọ́ wọn lọ́wọ́. Ìyẹn sì ni (ọlọ́hun) irọ́ wọn àti ohun tí wọ́n ń dá ní àdápa irọ́.

Verse 29

وَإِذْ صَرَفْنَآ إِلَيْكَ نَفَرًا مِّنَ ٱلْجِنِّ يَسْتَمِعُونَ ٱلْقُرْءَانَ فَلَمَّا حَضَرُوهُ قَالُوٓا۟ أَنصِتُوا۟ ۖ فَلَمَّا قُضِىَ وَلَّوْا۟ إِلَىٰ قَوْمِهِم مُّنذِرِينَ

Transliteration wa-idh ṣarafnā ilayka nafaran mina l-jini yastamiʿūna l-qur'āna falammā ḥaḍarūhu qālū anṣitū falammā quḍiya wallaw ilā qawmihim mundhirīna

Yoruba (Rántí) nígbà tí A darí ìjọ kan nínú àwọn àlùjànnú sí ọ, tí wọ́n ń tẹ́tí gbọ́ al-Ƙur’ān. Nígbà tí wọ́n dé síbẹ̀, wọ́n sọ pé: “Ẹ dákẹ́ (fún al-Ƙur’ān).” Nígbà tí wọ́n sì parí (kíké rẹ̀ tán), wọ́n padà sí ọ̀dọ̀ ìjọ wọn, tí wọ́n ń ṣèkìlọ̀ (fún wọn).

Verse 30

قَالُوا۟ يَـٰقَوْمَنَآ إِنَّا سَمِعْنَا كِتَـٰبًا أُنزِلَ مِنۢ بَعْدِ مُوسَىٰ مُصَدِّقًا لِّمَا بَيْنَ يَدَيْهِ يَهْدِىٓ إِلَى ٱلْحَقِّ وَإِلَىٰ طَرِيقٍ مُّسْتَقِيمٍ

Transliteration qālū yāqawmanā innā samiʿ'nā kitāban unzila min baʿdi mūsā muṣaddiqan limā bayna yadayhi yahdī ilā l-ḥaqi wa-ilā ṭarīqin mus'taqīmin

Yoruba Wọ́n sọ pé: “Ẹ̀yin ìjọ wa, dájúdájú àwa gbọ́ (nípa) Tírà kan tí wọ́n sọ̀kalẹ̀ lẹ́yìn (Ànábì) Mūsā, tí ó ń fi ohun tó jẹ́ òdodo rinlẹ̀ nípa èyí tó wá ṣíwájú rẹ̀, tí ó sì ń tọ́ni sí ọ̀nà òdodo àti ọ̀nà tààrà.

Verse 31

يَـٰقَوْمَنَآ أَجِيبُوا۟ دَاعِىَ ٱللَّهِ وَءَامِنُوا۟ بِهِۦ يَغْفِرْ لَكُم مِّن ذُنُوبِكُمْ وَيُجِرْكُم مِّنْ عَذَابٍ أَلِيمٍ

Transliteration yāqawmanā ajībū dāʿiya l-lahi waāminū bihi yaghfir lakum min dhunūbikum wayujir'kum min ʿadhābin alīmin

Yoruba Ẹ̀yin ìjọ wa, ẹ jẹ́ ìpè olùpèpè Allāhu. Kí ẹ sì gbà á gbọ́ ní òdodo. (Allāhu) yó sì forí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín jìn yín. Ó sì máa gbà yín là kúrò nínú ìyà ẹlẹ́ta-eléro.

Verse 32

وَمَن لَّا يُجِبْ دَاعِىَ ٱللَّهِ فَلَيْسَ بِمُعْجِزٍ فِى ٱلْأَرْضِ وَلَيْسَ لَهُۥ مِن دُونِهِۦٓ أَوْلِيَآءُ ۚ أُو۟لَـٰٓئِكَ فِى ضَلَـٰلٍ مُّبِينٍ

Transliteration waman lā yujib dāʿiya l-lahi falaysa bimuʿ'jizin fī l-arḍi walaysa lahu min dūnihi awliyāu ulāika fī ḍalālin mubīnin

Yoruba Ẹnikẹ́ni tí kò bá sì jẹ́pè olùpèpè Allāhu, kò lè mórí bọ́ mọ́ (Allāhu) lọ́wọ́ lórí ilẹ̀. Kò sì sí aláàbò kan fún un lẹ́yìn Allāhu. Àwọn wọ̀nyẹn sì wà nínú ìṣìnà pọ́nńbélé.”

Verse 33

أَوَلَمْ يَرَوْا۟ أَنَّ ٱللَّهَ ٱلَّذِى خَلَقَ ٱلسَّمَـٰوَٰتِ وَٱلْأَرْضَ وَلَمْ يَعْىَ بِخَلْقِهِنَّ بِقَـٰدِرٍ عَلَىٰٓ أَن يُحْـِۧىَ ٱلْمَوْتَىٰ ۚ بَلَىٰٓ إِنَّهُۥ عَلَىٰ كُلِّ شَىْءٍ قَدِيرٌ

Transliteration awalam yaraw anna l-laha alladhī khalaqa l-samāwāti wal-arḍa walam yaʿya bikhalqihinna biqādirin ʿalā an yuḥ'yiya l-mawtā balā innahu ʿalā kulli shayin qadīrun

Yoruba Ṣé wọn kò wòye pé dájúdájú Allāhu, Ẹni tí Ó dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀, tí kò sì káàárẹ̀ nípa ìṣẹ̀dá wọn, (ṣé kò) ní agbára láti sọ àwọn òkú di alààyè ni? Bẹ́ẹ̀ ni, (Ó lágbára láti ṣe bẹ́ẹ̀). Dájúdájú Ó ń jẹ́ Alágbára lórí gbogbo n̄ǹkan.

Verse 34

وَيَوْمَ يُعْرَضُ ٱلَّذِينَ كَفَرُوا۟ عَلَى ٱلنَّارِ أَلَيْسَ هَـٰذَا بِٱلْحَقِّ ۖ قَالُوا۟ بَلَىٰ وَرَبِّنَا ۚ قَالَ فَذُوقُوا۟ ٱلْعَذَابَ بِمَا كُنتُمْ تَكْفُرُونَ

Transliteration wayawma yuʿ'raḍu alladhīna kafarū ʿalā l-nāri alaysa hādhā bil-ḥaqi qālū balā warabbinā qāla fadhūqū l-ʿadhāba bimā kuntum takfurūna

Yoruba (Rántí) ọjọ́ tí wọ́n máa darí àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ kọ Iná, (wọ́n sì máa sọ fún wọn pé:) “Ṣé èyí kì í ṣe òdodo bí?” Wọn yóò wí pé: “Bẹ́ẹ̀ ni, (òdodo ni) Olúwa wa.” (Allāhu máa) sọ pé: “Nítorí náà, ẹ tọ́ ìyà wò nítorí pé, ẹ̀yin jẹ́ aláìgbàgbọ́.”

Verse 35

فَٱصْبِرْ كَمَا صَبَرَ أُو۟لُوا۟ ٱلْعَزْمِ مِنَ ٱلرُّسُلِ وَلَا تَسْتَعْجِل لَّهُمْ ۚ كَأَنَّهُمْ يَوْمَ يَرَوْنَ مَا يُوعَدُونَ لَمْ يَلْبَثُوٓا۟ إِلَّا سَاعَةً مِّن نَّهَارٍۭ ۚ بَلَـٰغٌ ۚ فَهَلْ يُهْلَكُ إِلَّا ٱلْقَوْمُ ٱلْفَـٰسِقُونَ

Transliteration fa-iṣ'bir kamā ṣabara ulū l-ʿazmi mina l-rusuli walā tastaʿjil lahum ka-annahum yawma yarawna mā yūʿadūna lam yalbathū illā sāʿatan min nahārin balāghun fahal yuh'laku illā l-qawmu l-fāsiqūna

Yoruba Nítorí náà, ṣe sùúrù gẹ́gẹ́ bí àwọn onípinnu ọkàn nínú àwọn Òjíṣẹ́ ti ṣe sùúrù. Má ṣe bá wọn wá ìyà pẹ̀lú ìkánjú. Ní ọjọ́ tí wọ́n bá rí ohun tí À ń ṣe ní àdéhùn fún wọn, wọn yóò dà bí ẹni pé wọn kò gbé ilé ayé (yìí) tayọ àkókò kan nínú ọ̀sán. Ìkéde (ẹ̀sìn nìyí fún wọn). Ta ni ó sì máa parun bí kò ṣe ìjọ òbìlẹ̀jẹ́.

Read Surah Al-Ahqaf in another language

All languages

All 114 surahs in Yoruba: the Qur’an in Yoruba.

Learn it in MyDugsi

Yoruba translation: Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni, from Quran.com. Transliteration: Quran.com. Recitation: Mishary Alafasy, from EveryAyah.com. MyDugsi is a learning aid, not a replacement for a qualified teacher.