MyDugsiStart learning

Surah Luqman in Yoruba: translation and audio

Surah 31 · لقمان · Luqman · 34 verses

Surah Luqman verse by verse: the Arabic with a recitation you can repeat, the transliteration, and the Yoruba translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni. For the meaning of every word, see Surah Luqman word by word in English.

Verse 1

الٓمٓ

Transliteration alif-lam-meem

Yoruba ’Alif lām mīm. (Allāhu ló mọ ohun tí Ó gbàlérò pẹ̀lú àwọn háràfí náà.)1

Verse 2

تِلْكَ ءَايَـٰتُ ٱلْكِتَـٰبِ ٱلْحَكِيمِ

Transliteration til'ka āyātu l-kitābi l-ḥakīmi

Yoruba Ìwọ̀nyí ni àwọn āyah Tírà tí ó kún fún ọgbọ́n.1

Verse 3

هُدًى وَرَحْمَةً لِّلْمُحْسِنِينَ

Transliteration hudan waraḥmatan lil'muḥ'sinīna

Yoruba (Ó jẹ́) ìmọ̀nà àti ìkẹ́ fún àwọn olùṣe-rere;

Verse 4

ٱلَّذِينَ يُقِيمُونَ ٱلصَّلَوٰةَ وَيُؤْتُونَ ٱلزَّكَوٰةَ وَهُم بِٱلْـَٔاخِرَةِ هُمْ يُوقِنُونَ

Transliteration alladhīna yuqīmūna l-ṣalata wayu'tūna l-zakata wahum bil-ākhirati hum yūqinūna

Yoruba àwọn tó ń kírun, tí wọ́n ń yọ zakāh. Àwọn sì ni wọ́n ní àmọ̀dájú nípa Ọjọ́ Ìkẹ́yìn.

Verse 5

أُو۟لَـٰٓئِكَ عَلَىٰ هُدًى مِّن رَّبِّهِمْ ۖ وَأُو۟لَـٰٓئِكَ هُمُ ٱلْمُفْلِحُونَ

Transliteration ulāika ʿalā hudan min rabbihim wa-ulāika humu l-muf'liḥūna

Yoruba Àwọn wọ̀nyẹn wà lórí ìmọ̀nà láti ọ̀dọ̀ Olúwa wọn. Àwọn wọ̀nyẹn sì ni àwọn olùjèrè.

Verse 6

وَمِنَ ٱلنَّاسِ مَن يَشْتَرِى لَهْوَ ٱلْحَدِيثِ لِيُضِلَّ عَن سَبِيلِ ٱللَّهِ بِغَيْرِ عِلْمٍ وَيَتَّخِذَهَا هُزُوًا ۚ أُو۟لَـٰٓئِكَ لَهُمْ عَذَابٌ مُّهِينٌ

Transliteration wamina l-nāsi man yashtarī lahwa l-ḥadīthi liyuḍilla ʿan sabīli l-lahi bighayri ʿil'min wayattakhidhahā huzuwan ulāika lahum ʿadhābun muhīnun

Yoruba Ó wà nínú àwọn ènìyàn, ẹni tó ń ra ọ̀rọ̀ eréláti fi ṣi àwọn ènìyàn lọ́nà kúrò lójú ọ̀nà (ẹ̀sìn) Allāhu pẹ̀lú àìnímọ̀ àti nítorí kí ó lè sọ ẹ̀sìn di yẹ̀yẹ́. Àwọn wọ̀nyẹn sì ni ìyà tí í yẹpẹrẹ ẹ̀dá wà fún.

Verse 7

وَإِذَا تُتْلَىٰ عَلَيْهِ ءَايَـٰتُنَا وَلَّىٰ مُسْتَكْبِرًا كَأَن لَّمْ يَسْمَعْهَا كَأَنَّ فِىٓ أُذُنَيْهِ وَقْرًا ۖ فَبَشِّرْهُ بِعَذَابٍ أَلِيمٍ

Transliteration wa-idhā tut'lā ʿalayhi āyātunā wallā mus'takbiran ka-an lam yasmaʿhā ka-anna fī udhunayhi waqran fabashir'hu biʿadhābin alīmin

Yoruba Àti pé nígbà tí wọ́n bá ń ké àwọn āyah Wa fún un, ó máa pẹ̀yìndà ní ti ìgbéraga, àfi bí ẹni pé kò gbọ́ ọ, àfi bí ẹni pé èdídí wà nínú etí rẹ̀ méjèèjì. Nítorí náà, fún un ní ìró ìyà ẹlẹ́ta-eléro.

Verse 8

إِنَّ ٱلَّذِينَ ءَامَنُوا۟ وَعَمِلُوا۟ ٱلصَّـٰلِحَـٰتِ لَهُمْ جَنَّـٰتُ ٱلنَّعِيمِ

Transliteration inna alladhīna āmanū waʿamilū l-ṣāliḥāti lahum jannātu l-naʿīmi

Yoruba Dájúdájú àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe iṣẹ́ rere, àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra ń bẹ fún wọn.

Verse 9

خَـٰلِدِينَ فِيهَا ۖ وَعْدَ ٱللَّهِ حَقًّا ۚ وَهُوَ ٱلْعَزِيزُ ٱلْحَكِيمُ

Transliteration khālidīna fīhā waʿda l-lahi ḥaqqan wahuwa l-ʿazīzu l-ḥakīmu

Yoruba Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀. (Ó jẹ́) àdéhùn Allāhu ní ti òdodo. Òun sì ni Alágbára, Ọlọ́gbọ́n.

Verse 10

خَلَقَ ٱلسَّمَـٰوَٰتِ بِغَيْرِ عَمَدٍ تَرَوْنَهَا ۖ وَأَلْقَىٰ فِى ٱلْأَرْضِ رَوَٰسِىَ أَن تَمِيدَ بِكُمْ وَبَثَّ فِيهَا مِن كُلِّ دَآبَّةٍ ۚ وَأَنزَلْنَا مِنَ ٱلسَّمَآءِ مَآءً فَأَنۢبَتْنَا فِيهَا مِن كُلِّ زَوْجٍ كَرِيمٍ

Transliteration khalaqa l-samāwāti bighayri ʿamadin tarawnahā wa-alqā fī l-arḍi rawāsiya an tamīda bikum wabatha fīhā min kulli dābbatin wa-anzalnā mina l-samāi māan fa-anbatnā fīhā min kulli zawjin karīmin

Yoruba Ó dá àwọn sánmọ̀ láì ní òpó tí ẹ lè rí. Ó sì ju àwọn àpáta tó dúró gbagidi sínú ilẹ̀ kí ó má fi lè mì mọ yín lẹ́sẹ̀. Ó fọ́n gbogbo n̄ǹkan abẹ̀mí ká sórí ilẹ̀. A tún sọ omi kalẹ̀ láti sánmọ̀, A sì fi mú gbogbo oríṣiríṣi èso dáadáa hù jáde láti inú ilẹ̀.

Verse 11

هَـٰذَا خَلْقُ ٱللَّهِ فَأَرُونِى مَاذَا خَلَقَ ٱلَّذِينَ مِن دُونِهِۦ ۚ بَلِ ٱلظَّـٰلِمُونَ فِى ضَلَـٰلٍ مُّبِينٍ

Transliteration hādhā khalqu l-lahi fa-arūnī mādhā khalaqa alladhīna min dūnihi bali l-ẓālimūna fī ḍalālin mubīnin

Yoruba Èyí ni ẹ̀dá ti Allāhu. Nítorí náà, ẹ fi ohun tí àwọn mìíràn lẹ́yìn Rẹ̀ dá hàn mí! Rárá o! Àwọn alábòsí wà nínú ìṣìnà pọ́nńbélé ni.

Verse 12

وَلَقَدْ ءَاتَيْنَا لُقْمَـٰنَ ٱلْحِكْمَةَ أَنِ ٱشْكُرْ لِلَّهِ ۚ وَمَن يَشْكُرْ فَإِنَّمَا يَشْكُرُ لِنَفْسِهِۦ ۖ وَمَن كَفَرَ فَإِنَّ ٱللَّهَ غَنِىٌّ حَمِيدٌ

Transliteration walaqad ātaynā luq'māna l-ḥik'mata ani ush'kur lillahi waman yashkur fa-innamā yashkuru linafsihi waman kafara fa-inna l-laha ghaniyyun ḥamīdun

Yoruba Dájúdájú A ti fún Luƙmọ̄n ní ọgbọ́n, pé: “Dúpẹ́ fún Allāhu.” Ẹnikẹ́ni tí ó bá dúpẹ́, ó ń dúpẹ́ fún ẹ̀mí ara rẹ̀ ni. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì ṣàì moore, dájúdájú Allāhu ni Ọlọ́rọ̀, Ẹlẹ́yìn (tí ẹyìn tọ́ sí).

Verse 13

وَإِذْ قَالَ لُقْمَـٰنُ لِٱبْنِهِۦ وَهُوَ يَعِظُهُۥ يَـٰبُنَىَّ لَا تُشْرِكْ بِٱللَّهِ ۖ إِنَّ ٱلشِّرْكَ لَظُلْمٌ عَظِيمٌ

Transliteration wa-idh qāla luq'mānu li-ib'nihi wahuwa yaʿiẓuhu yābunayya lā tush'rik bil-lahi inna l-shir'ka laẓul'mun ʿaẓīmun

Yoruba (Rántí) nígbà tí Luƙmọ̄n sọ fún ọmọ rẹ̀ nígbà tí ó ń ṣe wáàsí fún un, pé: “Ọmọ mi, má ṣe ṣẹbọ sí Allāhu. Dájúdájú ẹbọ ṣíṣe ni àbòsí ńlá.

Verse 14

وَوَصَّيْنَا ٱلْإِنسَـٰنَ بِوَٰلِدَيْهِ حَمَلَتْهُ أُمُّهُۥ وَهْنًا عَلَىٰ وَهْنٍ وَفِصَـٰلُهُۥ فِى عَامَيْنِ أَنِ ٱشْكُرْ لِى وَلِوَٰلِدَيْكَ إِلَىَّ ٱلْمَصِيرُ

Transliteration wawaṣṣaynā l-insāna biwālidayhi ḥamalathu ummuhu wahnan ʿalā wahnin wafiṣāluhu fī ʿāmayni ani ush'kur lī waliwālidayka ilayya l-maṣīru

Yoruba Àti pé A pa á ní àṣẹ fún ènìyàn nípa àwọn òbí rẹ̀ méjèèjì - ìyá rẹ̀ gbé e ká (nínú oyún) pẹ̀lú àìlera lórí àìlera, ó sì gba ọmú lẹ́nu rẹ̀ láààrin ọdún méjì - (A sọ) pé: “Dúpẹ́ fún Èmi àti àwọn òbí rẹ méjèèjì.” Ọ̀dọ̀ Mi sì ni àbọ̀ ẹ̀dá.

Verse 15

وَإِن جَـٰهَدَاكَ عَلَىٰٓ أَن تُشْرِكَ بِى مَا لَيْسَ لَكَ بِهِۦ عِلْمٌ فَلَا تُطِعْهُمَا ۖ وَصَاحِبْهُمَا فِى ٱلدُّنْيَا مَعْرُوفًا ۖ وَٱتَّبِعْ سَبِيلَ مَنْ أَنَابَ إِلَىَّ ۚ ثُمَّ إِلَىَّ مَرْجِعُكُمْ فَأُنَبِّئُكُم بِمَا كُنتُمْ تَعْمَلُونَ

Transliteration wa-in jāhadāka ʿalā an tush'rika bī mā laysa laka bihi ʿil'mun falā tuṭiʿ'humā waṣāḥib'humā fī l-dun'yā maʿrūfan wa-ittabiʿ sabīla man anāba ilayya thumma ilayya marjiʿukum fa-unabbi-ukum bimā kuntum taʿmalūna

Yoruba Tí àwọn méjèèjì bá sì jà ọ́ lógun pé kí ó fi ohun tí ìwọ kò ní ìmọ̀ nípa rẹ̀ ṣẹbọ sí Mi, má ṣe tẹ̀lé àwọn méjèèjì.Fi dáadáa bá àwọn méjèèjì lòpọ̀ ní ilé ayé.2 Kí o sì tẹ̀lé ojú ọ̀nà ẹni tí ó bá ṣẹ́rí padà sí ọ̀dọ̀ Mi (ní ti ìronúpìwàdà). Lẹ́yìn náà, ọ̀dọ̀ Mi ni ibùpadàsí yín. Nítorí náà, Mo máa fún yín ní ìró ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.

Verse 16

يَـٰبُنَىَّ إِنَّهَآ إِن تَكُ مِثْقَالَ حَبَّةٍ مِّنْ خَرْدَلٍ فَتَكُن فِى صَخْرَةٍ أَوْ فِى ٱلسَّمَـٰوَٰتِ أَوْ فِى ٱلْأَرْضِ يَأْتِ بِهَا ٱللَّهُ ۚ إِنَّ ٱللَّهَ لَطِيفٌ خَبِيرٌ

Transliteration yābunayya innahā in taku mith'qāla ḥabbatin min khardalin fatakun fī ṣakhratin aw fī l-samāwāti aw fī l-arḍi yati bihā l-lahu inna l-laha laṭīfun khabīrun

Yoruba Ọmọ mi, dájúdájú tí ó bá jẹ́ pé òdiwọ̀n èso kardal kanló wà nínú àpáta, tàbí nínú àwọn sánmọ̀, tàbí nínú ilẹ̀, Allāhu yóò mú un wá. Dájúdájú Allāhu ni Aláàánú, Alámọ̀tán.

Verse 17

يَـٰبُنَىَّ أَقِمِ ٱلصَّلَوٰةَ وَأْمُرْ بِٱلْمَعْرُوفِ وَٱنْهَ عَنِ ٱلْمُنكَرِ وَٱصْبِرْ عَلَىٰ مَآ أَصَابَكَ ۖ إِنَّ ذَٰلِكَ مِنْ عَزْمِ ٱلْأُمُورِ

Transliteration yābunayya aqimi l-ṣalata wamur bil-maʿrūfi wa-in'ha ʿani l-munkari wa-iṣ'bir ʿalā mā aṣābaka inna dhālika min ʿazmi l-umūri

Yoruba Ọmọ mi, kírun, p’àṣẹ rere, kọ aburú, kí o sì ṣe sùúrù lórí ohun tí ó bá ṣẹlẹ̀ sí ọ. Dájúdájú ìyẹn wà nínú àwọn ìpinnu ọ̀rọ̀ tó pọn dandan.

Verse 18

وَلَا تُصَعِّرْ خَدَّكَ لِلنَّاسِ وَلَا تَمْشِ فِى ٱلْأَرْضِ مَرَحًا ۖ إِنَّ ٱللَّهَ لَا يُحِبُّ كُلَّ مُخْتَالٍ فَخُورٍ

Transliteration walā tuṣaʿʿir khaddaka lilnnāsi walā tamshi fī l-arḍi maraḥan inna l-laha lā yuḥibbu kulla mukh'tālin fakhūrin

Yoruba Má ṣe kọ párìkẹ́ rẹ sí ènìyàn. Má sì ṣe rìn lórí ilẹ̀ pẹ̀lú fáàrí. Dájúdájú Allāhu kò fẹ́ràn gbogbo onígbèéraga, onífáàrí.

Verse 19

وَٱقْصِدْ فِى مَشْيِكَ وَٱغْضُضْ مِن صَوْتِكَ ۚ إِنَّ أَنكَرَ ٱلْأَصْوَٰتِ لَصَوْتُ ٱلْحَمِيرِ

Transliteration wa-iq'ṣid fī mashyika wa-ugh'ḍuḍ min ṣawtika inna ankara l-aṣwāti laṣawtu l-ḥamīri

Yoruba Jẹ́ kí ìrìn ẹsẹ̀ rẹ wà ní ìwọ̀ntún-wọ̀nsì, kí o sì rẹ ohùn rẹ nílẹ̀. Dájúdájú ohùn tó burú jùlọ mà ni ohùn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́.”

Verse 20

أَلَمْ تَرَوْا۟ أَنَّ ٱللَّهَ سَخَّرَ لَكُم مَّا فِى ٱلسَّمَـٰوَٰتِ وَمَا فِى ٱلْأَرْضِ وَأَسْبَغَ عَلَيْكُمْ نِعَمَهُۥ ظَـٰهِرَةً وَبَاطِنَةً ۗ وَمِنَ ٱلنَّاسِ مَن يُجَـٰدِلُ فِى ٱللَّهِ بِغَيْرِ عِلْمٍ وَلَا هُدًى وَلَا كِتَـٰبٍ مُّنِيرٍ

Transliteration alam taraw anna l-laha sakhara lakum mā fī l-samāwāti wamā fī l-arḍi wa-asbagha ʿalaykum niʿamahu ẓāhiratan wabāṭinatan wamina l-nāsi man yujādilu fī l-lahi bighayri ʿil'min walā hudan walā kitābin munīrin

Yoruba Ṣé ẹ kò wòye pé, dájúdájú Allāhu rọ ohunkóhun tó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ohunkóhun tó wà nínú ilẹ̀ fún yín, Ó sì pé àwọn ìkẹ́ Rẹ̀ fún yín ní gban̄gba àti ní kọ̀rọ̀? Ó sì wà nínú àwọn ènìyàn ẹni tó ń jiyàn nípa Allāhu láì ní ìmọ̀ (al-Ƙur’ān) àti ìmọ̀nà (nínú sunnah Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -) àti tírà (onímọ̀-ẹ̀sìn) tó ń tan ìmọ́lẹ̀ (sí ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn).

Verse 21

وَإِذَا قِيلَ لَهُمُ ٱتَّبِعُوا۟ مَآ أَنزَلَ ٱللَّهُ قَالُوا۟ بَلْ نَتَّبِعُ مَا وَجَدْنَا عَلَيْهِ ءَابَآءَنَآ ۚ أَوَلَوْ كَانَ ٱلشَّيْطَـٰنُ يَدْعُوهُمْ إِلَىٰ عَذَابِ ٱلسَّعِيرِ

Transliteration wa-idhā qīla lahumu ittabiʿū mā anzala l-lahu qālū bal nattabiʿu mā wajadnā ʿalayhi ābāanā awalaw kāna l-shayṭānu yadʿūhum ilā ʿadhābi l-saʿīri

Yoruba Nígbà tí wọ́n bá sì sọ fún wọn pé: “Ẹ tẹ̀lé ohun tí Allāhu sọ̀kalẹ̀.” Wọ́n á wí pé: “Rárá! A máa tẹ̀lé ohun tí a bá lọ́wọ́ àwọn bàbá wa ni.” (Ṣé wọn yóò tẹ̀lé àwọn bàbá wọn) t’òhun ti bí Èṣù ṣe ń pè wọ́n síbi ìyà Iná tó ń jò fòfò?

Verse 22

۞ وَمَن يُسْلِمْ وَجْهَهُۥٓ إِلَى ٱللَّهِ وَهُوَ مُحْسِنٌ فَقَدِ ٱسْتَمْسَكَ بِٱلْعُرْوَةِ ٱلْوُثْقَىٰ ۗ وَإِلَى ٱللَّهِ عَـٰقِبَةُ ٱلْأُمُورِ

Transliteration waman yus'lim wajhahu ilā l-lahi wahuwa muḥ'sinun faqadi is'tamsaka bil-ʿur'wati l-wuth'qā wa-ilā l-lahi ʿāqibatu l-umūri

Yoruba Ẹnikẹ́ni tí ó bá jura rẹ̀ sílẹ̀ fún Allāhu, tí ó jẹ́ olùṣe-rere, dájúdájú onítọ̀un ti dìrọ̀ mọ́ okùn tó fọkàn balẹ̀ jùlọ. Àti pé ọ̀dọ̀ Allāhu ni ìkángun àwọn ọ̀rọ̀ (ẹ̀dá) wà.

Verse 23

وَمَن كَفَرَ فَلَا يَحْزُنكَ كُفْرُهُۥٓ ۚ إِلَيْنَا مَرْجِعُهُمْ فَنُنَبِّئُهُم بِمَا عَمِلُوٓا۟ ۚ إِنَّ ٱللَّهَ عَلِيمٌۢ بِذَاتِ ٱلصُّدُورِ

Transliteration waman kafara falā yaḥzunka kuf'ruhu ilaynā marjiʿuhum fanunabbi-uhum bimā ʿamilū inna l-laha ʿalīmun bidhāti l-ṣudūri

Yoruba Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì ṣàì gbàgbọ́, má ṣe jẹ́ kí àìgbàgbọ́ rẹ̀ kó ìbànújẹ́ bá ọ. Ọ̀dọ̀ Wa ni ibùpadàsí wọn. Nígbà náà, A máa fún wọn ní ìró ohun tí wọ́n ṣe níṣẹ́. Dájúdájú Allāhu ni Onímọ̀ nípa ohun tí ń bẹ nínú igbá-àyà ẹ̀dá.

Verse 24

نُمَتِّعُهُمْ قَلِيلًا ثُمَّ نَضْطَرُّهُمْ إِلَىٰ عَذَابٍ غَلِيظٍ

Transliteration numattiʿuhum qalīlan thumma naḍṭarruhum ilā ʿadhābin ghalīẓin

Yoruba A máa fún wọn ní ìgbádùn díẹ̀. Lẹ́yìn náà, A máa taari wọn sínú ìyà tó nípọn.

Verse 25

وَلَئِن سَأَلْتَهُم مَّنْ خَلَقَ ٱلسَّمَـٰوَٰتِ وَٱلْأَرْضَ لَيَقُولُنَّ ٱللَّهُ ۚ قُلِ ٱلْحَمْدُ لِلَّهِ ۚ بَلْ أَكْثَرُهُمْ لَا يَعْلَمُونَ

Transliteration wala-in sa-altahum man khalaqa l-samāwāti wal-arḍa layaqūlunna l-lahu quli l-ḥamdu lillahi bal aktharuhum lā yaʿlamūna

Yoruba Dájúdájú tí o bá bi wọ́n léèrè pé: “Ta ni Ó dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀?”, dájúdájú wọ́n á wí pé: “Allāhu ni.” Sọ pé: “Gbogbo ẹyìn ń jẹ́ ti Allāhu, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn kò mọ̀.

Verse 26

لِلَّهِ مَا فِى ٱلسَّمَـٰوَٰتِ وَٱلْأَرْضِ ۚ إِنَّ ٱللَّهَ هُوَ ٱلْغَنِىُّ ٱلْحَمِيدُ

Transliteration lillahi mā fī l-samāwāti wal-arḍi inna l-laha huwa l-ghaniyu l-ḥamīdu

Yoruba Ti Allāhu ni ohunkóhun tó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Dájúdájú Allāhu, Òun ni Ọlọ́rọ̀, Ẹlẹ́yìn.

Verse 27

وَلَوْ أَنَّمَا فِى ٱلْأَرْضِ مِن شَجَرَةٍ أَقْلَـٰمٌ وَٱلْبَحْرُ يَمُدُّهُۥ مِنۢ بَعْدِهِۦ سَبْعَةُ أَبْحُرٍ مَّا نَفِدَتْ كَلِمَـٰتُ ٱللَّهِ ۗ إِنَّ ٱللَّهَ عَزِيزٌ حَكِيمٌ

Transliteration walaw annamā fī l-arḍi min shajaratin aqlāmun wal-baḥru yamudduhu min baʿdihi sabʿatu abḥurin mā nafidat kalimātu l-lahi inna l-laha ʿazīzun ḥakīmun

Yoruba Tí ó bá jẹ́ pé kìkìdá ohun tó ń bẹ lórí ilẹ̀ ní igi ni gègé ìkọ̀wé, kí agbami odò jẹ́ tàdáà rẹ̀, agbami odò méje (tún wà) lẹ́yìn rẹ̀ (tó máa kún un), àwọn ọ̀rọ̀ Allāhu kò níí tán (lẹ́yìn tí àwọn n̄ǹkan ìkọ̀wé wọ̀nyí bá tán nílẹ̀). Dájúdájú Allāhu ni Alágbára, Ọlọ́gbọ́n.

Verse 28

مَّا خَلْقُكُمْ وَلَا بَعْثُكُمْ إِلَّا كَنَفْسٍ وَٰحِدَةٍ ۗ إِنَّ ٱللَّهَ سَمِيعٌۢ بَصِيرٌ

Transliteration mā khalqukum walā baʿthukum illā kanafsin wāḥidatin inna l-laha samīʿun baṣīrun

Yoruba Ìṣẹ̀dá yín àti àjíǹde yín kò tayọ bí (ìṣẹ̀dá àti àjíǹde) ẹ̀mí ẹyọ kan. Dájúdájú Allāhu ni Olùgbọ́, Olùríran.

Verse 29

أَلَمْ تَرَ أَنَّ ٱللَّهَ يُولِجُ ٱلَّيْلَ فِى ٱلنَّهَارِ وَيُولِجُ ٱلنَّهَارَ فِى ٱلَّيْلِ وَسَخَّرَ ٱلشَّمْسَ وَٱلْقَمَرَ كُلٌّ يَجْرِىٓ إِلَىٰٓ أَجَلٍ مُّسَمًّى وَأَنَّ ٱللَّهَ بِمَا تَعْمَلُونَ خَبِيرٌ

Transliteration alam tara anna l-laha yūliju al-layla fī l-nahāri wayūliju l-nahāra fī al-layli wasakhara l-shamsa wal-qamara kullun yajrī ilā ajalin musamman wa-anna l-laha bimā taʿmalūna khabīrun

Yoruba Ṣé o ò rí i pé dájúdájú Allāhu l’Ó ń ti òru bọ inú ọ̀sán, Ó ń ti ọ̀sán bọ inú òru, Ó sì rọ òòrùn àti òṣùpá? Ìkọ̀ọ̀kan wọn máa rìn títí di gbèdéke àkókò kan.Àti pé (ṣé o ò rí i pé) dájúdájú Allāhu ni Alámọ̀tán nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́?

Verse 30

ذَٰلِكَ بِأَنَّ ٱللَّهَ هُوَ ٱلْحَقُّ وَأَنَّ مَا يَدْعُونَ مِن دُونِهِ ٱلْبَـٰطِلُ وَأَنَّ ٱللَّهَ هُوَ ٱلْعَلِىُّ ٱلْكَبِيرُ

Transliteration dhālika bi-anna l-laha huwa l-ḥaqu wa-anna mā yadʿūna min dūnihi l-bāṭilu wa-anna l-laha huwa l-ʿaliyu l-kabīru

Yoruba Ìyẹn nítorí pé, dájúdájú Allāhu, Òun ni Òdodo. Àti pé dájúdájú ohun tí wọ́n ń pè lẹ́yìn Rẹ̀ ni irọ́. Dájúdájú Allāhu, Ó ga, Ó tóbi.

Verse 31

أَلَمْ تَرَ أَنَّ ٱلْفُلْكَ تَجْرِى فِى ٱلْبَحْرِ بِنِعْمَتِ ٱللَّهِ لِيُرِيَكُم مِّنْ ءَايَـٰتِهِۦٓ ۚ إِنَّ فِى ذَٰلِكَ لَـَٔايَـٰتٍ لِّكُلِّ صَبَّارٍ شَكُورٍ

Transliteration alam tara anna l-ful'ka tajrī fī l-baḥri biniʿ'mati l-lahi liyuriyakum min āyātihi inna fī dhālika laāyātin likulli ṣabbārin shakūrin

Yoruba Ṣé o ò rí i pé dájúdájú ọkọ̀ ojú-omi ń rìn ní ojú omi pẹ̀lú ìdẹ̀ra Rẹ̀, (ṣebí) nítorí kí (Allāhu) lè fi hàn yín nínú àwọn àmì Rẹ̀ ni? Dájúdájú àwọn àmì wà nínú ìyẹn fún gbogbo onísùúrù, olùdúpẹ́.

Verse 32

وَإِذَا غَشِيَهُم مَّوْجٌ كَٱلظُّلَلِ دَعَوُا۟ ٱللَّهَ مُخْلِصِينَ لَهُ ٱلدِّينَ فَلَمَّا نَجَّىٰهُمْ إِلَى ٱلْبَرِّ فَمِنْهُم مُّقْتَصِدٌ ۚ وَمَا يَجْحَدُ بِـَٔايَـٰتِنَآ إِلَّا كُلُّ خَتَّارٍ كَفُورٍ

Transliteration wa-idhā ghashiyahum mawjun kal-ẓulali daʿawū l-laha mukh'liṣīna lahu l-dīna falammā najjāhum ilā l-bari famin'hum muq'taṣidun wamā yajḥadu biāyātinā illā kullu khattārin kafūrin

Yoruba Nígbà tí ìgbì omi bá bò wọ́n mọ́lẹ̀ dáru bí ẹ̀ṣújò, wọ́n máa pe Allāhu lẹ́ni tí yóò máa fi àfọ̀mọ́-ọkàn (àníyàn mímọ́) ṣe ẹ̀sìn fún Un.Nígbà tí Ó bá sì gbà wọ́n là sórí ilẹ̀, onídéédé sì máa wà nínú wọn. Kò sì sí ẹni tó máa tako àwọn āyah Wa àfi gbogbo ọ̀dàlẹ̀, aláìmoore.

Verse 33

يَـٰٓأَيُّهَا ٱلنَّاسُ ٱتَّقُوا۟ رَبَّكُمْ وَٱخْشَوْا۟ يَوْمًا لَّا يَجْزِى وَالِدٌ عَن وَلَدِهِۦ وَلَا مَوْلُودٌ هُوَ جَازٍ عَن وَالِدِهِۦ شَيْـًٔا ۚ إِنَّ وَعْدَ ٱللَّهِ حَقٌّ ۖ فَلَا تَغُرَّنَّكُمُ ٱلْحَيَوٰةُ ٱلدُّنْيَا وَلَا يَغُرَّنَّكُم بِٱللَّهِ ٱلْغَرُورُ

Transliteration yāayyuhā l-nāsu ittaqū rabbakum wa-ikh'shaw yawman lā yajzī wālidun ʿan waladihi walā mawlūdun huwa jāzin ʿan wālidihi shayan inna waʿda l-lahi ḥaqqun falā taghurrannakumu l-ḥayatu l-dun'yā walā yaghurrannakum bil-lahi l-gharūru

Yoruba Ẹ̀yin ènìyàn, ẹ bẹ̀rù Olúwa yín. Kí ẹ sì páyà ọjọ́ kan tí òbí kan kò níí ṣàǹfààní fún ọmọ rẹ̀; àti pé ọmọ kan, òun náà kò níí ṣàǹfààní kiní kan fún òbí rẹ̀. Dájúdájú àdéhùn Allāhu ni òdodo. Nítorí náà, ìṣẹ̀mí ayé yìí kò gbọdọ̀ tàn yín jẹ. (Èṣù) ẹlẹ́tàn kò sì gbọdọ̀ tàn yín jẹ nípa Allāhu.

Verse 34

إِنَّ ٱللَّهَ عِندَهُۥ عِلْمُ ٱلسَّاعَةِ وَيُنَزِّلُ ٱلْغَيْثَ وَيَعْلَمُ مَا فِى ٱلْأَرْحَامِ ۖ وَمَا تَدْرِى نَفْسٌ مَّاذَا تَكْسِبُ غَدًا ۖ وَمَا تَدْرِى نَفْسٌۢ بِأَىِّ أَرْضٍ تَمُوتُ ۚ إِنَّ ٱللَّهَ عَلِيمٌ خَبِيرٌۢ

Transliteration inna l-laha ʿindahu ʿil'mu l-sāʿati wayunazzilu l-ghaytha wayaʿlamu mā fī l-arḥāmi wamā tadrī nafsun mādhā taksibu ghadan wamā tadrī nafsun bi-ayyi arḍin tamūtu inna l-laha ʿalīmun khabīrun

Yoruba Dájúdájú Allāhu, ọ̀dọ̀ Rẹ̀ ni ìmọ̀ Àkókò náà wà. Ó ń sọ òjò kalẹ̀. Ó mọ ohun tó wà nínú àpòlùkẹ́.Ẹ̀mí kan kò sì mọ ohun tí ó máa ṣe níṣẹ́ ní ọ̀la. Ẹ̀mí kan kò sì mọ ilẹ̀ wo l’ó máa kú sí. Dájúdájú Allāhu ni Onímọ̀, Alámọ̀tán.

Read Surah Luqman in another language

All languages

All 114 surahs in Yoruba: the Qur’an in Yoruba.

Learn it in MyDugsi

Yoruba translation: Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni, from Quran.com. Transliteration: Quran.com. Recitation: Mishary Alafasy, from EveryAyah.com. MyDugsi is a learning aid, not a replacement for a qualified teacher.