Surah Ash-Shams in Yoruba: translation and audio
Surah 91 · الشمس · The Sun · 15 verses
Surah Ash-Shams verse by verse: the Arabic with a recitation you can repeat, the transliteration, and the Yoruba translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni. For the meaning of every word, see Surah Ash-Shams word by word in English.
Verse 1
وَٱلشَّمْسِ وَضُحَىٰهَا
Transliteration wal-shamsi waḍuḥāhā
Yoruba Allāhu fi òòrùn àti ìyálẹ̀ta rẹ̀ búra.
Verse 2
وَٱلْقَمَرِ إِذَا تَلَىٰهَا
Transliteration wal-qamari idhā talāhā
Yoruba Ó tún fi òṣùpá nígbà tí ó bá (yọ) tẹ̀lé (òòrùn) búra.
Verse 3
وَٱلنَّهَارِ إِذَا جَلَّىٰهَا
Transliteration wal-nahāri idhā jallāhā
Yoruba Ó tún fi ọ̀sán nígbà tí ó bá mú ìmọ́lẹ̀ bá òkùnkùn òru búra.
Verse 4
وَٱلَّيْلِ إِذَا يَغْشَىٰهَا
Transliteration wa-al-layli idhā yaghshāhā
Yoruba Ó tún fi alẹ́ nígbà tí ó bá bo ọ̀sán mọ́lẹ̀ búra.
Verse 5
وَٱلسَّمَآءِ وَمَا بَنَىٰهَا
Transliteration wal-samāi wamā banāhā
Yoruba Ó tún fi sánmọ̀ àti Ẹni tí Ó mọ ọ́nbúra?
Verse 6
وَٱلْأَرْضِ وَمَا طَحَىٰهَا
Transliteration wal-arḍi wamā ṭaḥāhā
Yoruba Ó tún fi ilẹ̀ àti Ẹni tí Ó tẹ́ ẹ kalẹ̀ pẹrẹsẹ búra.
Verse 7
وَنَفْسٍ وَمَا سَوَّىٰهَا
Transliteration wanafsin wamā sawwāhā
Yoruba Ó tún fi ẹ̀mí (ènìyàn) àti Ẹni tí Ó ṣe (oríkèé rẹ̀) dọ́gba búra.
Verse 8
فَأَلْهَمَهَا فُجُورَهَا وَتَقْوَىٰهَا
Transliteration fa-alhamahā fujūrahā wataqwāhā
Yoruba Ó sì fi ẹ̀ṣẹ̀ (tí ẹ̀mí lè dá) àti ìbẹ̀rù rẹ̀ mọ̀ ọ́n.
Verse 9
قَدْ أَفْلَحَ مَن زَكَّىٰهَا
Transliteration qad aflaḥa man zakkāhā
Yoruba Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe àfọ̀mọ́ (ẹ̀mí ara) rẹ̀ (níbi ẹ̀ṣẹ̀), ó mà ti jèrè.1
Verse 10
وَقَدْ خَابَ مَن دَسَّىٰهَا
Transliteration waqad khāba man dassāhā
Yoruba Ẹnikẹ́ni tí ó bá fi (ìwà ẹ̀ṣẹ̀) ba ẹ̀mí (ara) rẹ̀ jẹ́, ó mà ti pàdánù.
Verse 11
كَذَّبَتْ ثَمُودُ بِطَغْوَىٰهَآ
Transliteration kadhabat thamūdu biṭaghwāhā
Yoruba Ìjọ Thamūd pe òdodo ní irọ́ nípa ìtayọ ẹnu-ààlà wọn.
Verse 12
إِذِ ٱنۢبَعَثَ أَشْقَىٰهَا
Transliteration idhi inbaʿatha ashqāhā
Yoruba (Rántí) nígbà tí ẹni tí orí rẹ̀ burú jùlọ nínú wọn sáré dìde (láti gún ràkúnmí pa).
Verse 13
فَقَالَ لَهُمْ رَسُولُ ٱللَّهِ نَاقَةَ ٱللَّهِ وَسُقْيَـٰهَا
Transliteration faqāla lahum rasūlu l-lahi nāqata l-lahi wasuq'yāhā
Yoruba Nígbà náà, Òjíṣẹ́ Allāhu sọ fún wọn pé: “(Ẹ fi) abo ràkúnmí Allāhu àti omi rẹ̀ (sílẹ̀).”
Verse 14
فَكَذَّبُوهُ فَعَقَرُوهَا فَدَمْدَمَ عَلَيْهِمْ رَبُّهُم بِذَنۢبِهِمْ فَسَوَّىٰهَا
Transliteration fakadhabūhu faʿaqarūhā fadamdama ʿalayhim rabbuhum bidhanbihim fasawwāhā
Yoruba Wọ́n pè é ní òpùrọ́. Wọ́n sì gún (ràkúnmí) pa. Nítorí náà, Olúwa wọn pa wọ́n rẹ́ nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Ó sì fi ìparun náà kárí wọn.
Verse 15
وَلَا يَخَافُ عُقْبَـٰهَا
Transliteration walā yakhāfu ʿuq'bāhā
Yoruba (Ẹni tó gún ràkúnmí pa) kò sì páyà ìkángun ọ̀rọ̀ wọn.
Read Surah Ash-Shams in another language
- English (word by word)
- Albanian
- Amazigh
- Amharic
- Assamese
- Azerbaijani
- Bambara
- Bangla
- Bosnian
- Bulgarian
- Chechen
- Chinese
- Czech
- Dari
- Dhivehi
- Dutch
- Finnish
- French
- German
- Gujarati
- Hausa
- Hebrew
- Hindi
- Indonesian
- Italian
- Japanese
- Kannada
- Kazakh
- Khmer
- Kinyarwanda
- Korean
- Kurdish
- Luganda
- Malay
- Malayalam
- Maranao
- Marathi
- Nepali
- Norwegian
- Oromo
- Pashto
- Persian
- Polish
- Portuguese
- Romanian
- Russian
- Sindhi
- Sinhala
- Somali
- Spanish
- Swahili
- Swedish
- Tagalog
- Tajik
- Tamil
- Tatar
- Telugu
- Thai
- Turkish
- Ukrainian
- Urdu
- Uyghur
- Uzbek
- Vietnamese
- Yao
All 114 surahs in Yoruba: the Qur’an in Yoruba.
Yoruba translation: Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni, from Quran.com. Transliteration: Quran.com. Recitation: Mishary Alafasy, from EveryAyah.com. MyDugsi is a learning aid, not a replacement for a qualified teacher.