MyDugsiStart learning

Surah Al-Inshiqaq in Yoruba: translation and audio

Surah 84 · الإنشقاق · The Sundering · 25 verses

Surah Al-Inshiqaq verse by verse: the Arabic with a recitation you can repeat, the transliteration, and the Yoruba translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni. For the meaning of every word, see Surah Al-Inshiqaq word by word in English.

Verse 1

إِذَا ٱلسَّمَآءُ ٱنشَقَّتْ

Transliteration idhā l-samāu inshaqqat

Yoruba Nígbà tí sánmọ̀ bá fàya pẹ́rẹpẹ̀rẹ

Verse 2

وَأَذِنَتْ لِرَبِّهَا وَحُقَّتْ

Transliteration wa-adhinat lirabbihā waḥuqqat

Yoruba - ó gbọ́, ó sì tẹ̀lé àṣẹ Olúwa rẹ̀ ni. Ó sì di dandan fún un láti ṣe bẹ́ẹ̀-

Verse 3

وَإِذَا ٱلْأَرْضُ مُدَّتْ

Transliteration wa-idhā l-arḍu muddat

Yoruba àti nígbà tí A bá fẹ ilẹ̀ lójú,

Verse 4

وَأَلْقَتْ مَا فِيهَا وَتَخَلَّتْ

Transliteration wa-alqat mā fīhā watakhallat

Yoruba ó máa ju ohun tí ó wà nínú rẹ̀ síta, ó sì máa pa sófo

Verse 5

وَأَذِنَتْ لِرَبِّهَا وَحُقَّتْ

Transliteration wa-adhinat lirabbihā waḥuqqat

Yoruba - ó gbọ́, ó sì tẹ̀lé àṣẹ Olúwa rẹ̀ ni. Ó sì di dandan fún un láti ṣe bẹ́ẹ̀ - (ní ọjọ́ yẹn ni ẹ̀dá máa rí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀)

Verse 6

يَـٰٓأَيُّهَا ٱلْإِنسَـٰنُ إِنَّكَ كَادِحٌ إِلَىٰ رَبِّكَ كَدْحًا فَمُلَـٰقِيهِ

Transliteration yāayyuhā l-insānu innaka kādiḥun ilā rabbika kadḥan famulāqīhi

Yoruba Ìwọ ènìyàn dájúdájú ìwọ ń ṣe iṣẹ́ kárakára ní iṣẹ́ àṣepàdé Olúwa rẹ. O sì máa mú un pàdé Rẹ̀.

Verse 7

فَأَمَّا مَنْ أُوتِىَ كِتَـٰبَهُۥ بِيَمِينِهِۦ

Transliteration fa-ammā man ūtiya kitābahu biyamīnihi

Yoruba Nítorí náà, ní ti ẹni tí wọ́n bá fún ní ìwé iṣẹ́ rẹ̀ ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀,

Verse 8

فَسَوْفَ يُحَاسَبُ حِسَابًا يَسِيرًا

Transliteration fasawfa yuḥāsabu ḥisāban yasīran

Yoruba láìpẹ́ A máa ṣe ìṣírò-iṣẹ́ (rẹ̀) ní ìṣírò ìrọ̀rùn.

Verse 9

وَيَنقَلِبُ إِلَىٰٓ أَهْلِهِۦ مَسْرُورًا

Transliteration wayanqalibu ilā ahlihi masrūran

Yoruba Ó sì máa padà sí ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn rẹ̀ (nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra) lẹ́ni ìdùnnú.

Verse 10

وَأَمَّا مَنْ أُوتِىَ كِتَـٰبَهُۥ وَرَآءَ ظَهْرِهِۦ

Transliteration wa-ammā man ūtiya kitābahu warāa ẓahrihi

Yoruba Ní ti ẹni tí wọ́n bá sì fún ní ìwé iṣẹ́ rẹ̀ láti ẹ̀yìn rẹ̀,1

Verse 11

فَسَوْفَ يَدْعُوا۟ ثُبُورًا

Transliteration fasawfa yadʿū thubūran

Yoruba láìpẹ́ ó máa kígbe ìparun.

Verse 12

وَيَصْلَىٰ سَعِيرًا

Transliteration wayaṣlā saʿīran

Yoruba Ó sì máa wọ inú Iná tó ń jó.

Verse 13

إِنَّهُۥ كَانَ فِىٓ أَهْلِهِۦ مَسْرُورًا

Transliteration innahu kāna fī ahlihi masrūran

Yoruba Dájúdájú ó ti wà láààrin àwọn ènìyàn rẹ̀ lẹ́ni ìdùnnú (sí àìgbàgbọ́ nílé ayé).

Verse 14

إِنَّهُۥ ظَنَّ أَن لَّن يَحُورَ

Transliteration innahu ẓanna an lan yaḥūra

Yoruba Dájúdájú ó lérò pé òun kò níí padà (sí ọ̀dọ̀ Allāhu ni).

Verse 15

بَلَىٰٓ إِنَّ رَبَّهُۥ كَانَ بِهِۦ بَصِيرًا

Transliteration balā inna rabbahu kāna bihi baṣīran

Yoruba Bẹ́ẹ̀ ni, (ó máa padà). Dájúdájú Olúwa rẹ̀ jẹ́ Olùríran nípa rẹ̀.

Verse 16

فَلَآ أُقْسِمُ بِٱلشَّفَقِ

Transliteration falā uq'simu bil-shafaqi

Yoruba Nítorí náà, Èmi (Allāhu) ń fi àwòǹpapa búra.

Verse 17

وَٱلَّيْلِ وَمَا وَسَقَ

Transliteration wa-al-layli wamā wasaqa

Yoruba Mo tún ń fi òru àti ohun tí ó kó jọ sínú rẹ̀ búra.

Verse 18

وَٱلْقَمَرِ إِذَا ٱتَّسَقَ

Transliteration wal-qamari idhā ittasaqa

Yoruba Mo tún ń fi òṣùpá nígbà tí ó bá dégbá (tí ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ kún) búra.

Verse 19

لَتَرْكَبُنَّ طَبَقًا عَن طَبَقٍ

Transliteration latarkabunna ṭabaqan ʿan ṭabaqin

Yoruba Dájúdájú ẹ̀yin yóò máa bọ́ sínú wàhálà kan láti inú wàhálà kan.

Verse 20

فَمَا لَهُمْ لَا يُؤْمِنُونَ

Transliteration famā lahum lā yu'minūna

Yoruba Kí l’ó ṣe wọ́n ná tí wọn kò fi gbàgbọ́ ní òdodo?

Verse 21

وَإِذَا قُرِئَ عَلَيْهِمُ ٱلْقُرْءَانُ لَا يَسْجُدُونَ ۩

Transliteration wa-idhā quri-a ʿalayhimu l-qur'ānu lā yasjudūna

Yoruba Nígbà tí wọ́n bá sì ké al-Ƙur’ān fún wọn, wọn kò níí forí kanlẹ̀.

Verse 22

بَلِ ٱلَّذِينَ كَفَرُوا۟ يُكَذِّبُونَ

Transliteration bali alladhīna kafarū yukadhibūna

Yoruba Rárá, ńṣe ni àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ ń pè é ní irọ́.

Verse 23

وَٱللَّهُ أَعْلَمُ بِمَا يُوعُونَ

Transliteration wal-lahu aʿlamu bimā yūʿūna

Yoruba Allāhu sì nímọ̀ jùlọ nípa ohun tí wọ́n ń fi pamọ́ (sínú ọkàn wọn).

Verse 24

فَبَشِّرْهُم بِعَذَابٍ أَلِيمٍ

Transliteration fabashir'hum biʿadhābin alīmin

Yoruba Nítorí náà, fún wọn ní ìró ìyà ẹlẹ́ta-eléro.

Verse 25

إِلَّا ٱلَّذِينَ ءَامَنُوا۟ وَعَمِلُوا۟ ٱلصَّـٰلِحَـٰتِ لَهُمْ أَجْرٌ غَيْرُ مَمْنُونٍۭ

Transliteration illā alladhīna āmanū waʿamilū l-ṣāliḥāti lahum ajrun ghayru mamnūnin

Yoruba Àyàfi àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe àwọn iṣẹ́ rere, ẹ̀san tí kò níí pinń bẹ fún wọn.

Read Surah Al-Inshiqaq in another language

All languages

All 114 surahs in Yoruba: the Qur’an in Yoruba.

Learn it in MyDugsi

Yoruba translation: Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni, from Quran.com. Transliteration: Quran.com. Recitation: Mishary Alafasy, from EveryAyah.com. MyDugsi is a learning aid, not a replacement for a qualified teacher.