MyDugsiStart learning

Surah Al-Infitar in Yoruba: translation and audio

Surah 82 · الإنفطار · The Cleaving · 19 verses

Surah Al-Infitar verse by verse: the Arabic with a recitation you can repeat, the transliteration, and the Yoruba translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni. For the meaning of every word, see Surah Al-Infitar word by word in English.

Verse 1

إِذَا ٱلسَّمَآءُ ٱنفَطَرَتْ

Transliteration idhā l-samāu infaṭarat

Yoruba Nígbà tí sánmọ̀ bá fàya pẹ́rẹpẹ̀rẹ,1

Verse 2

وَإِذَا ٱلْكَوَاكِبُ ٱنتَثَرَتْ

Transliteration wa-idhā l-kawākibu intatharat

Yoruba àti nígbà tí àwọn ìràwọ̀ bá já bọ́ káàkiri,

Verse 3

وَإِذَا ٱلْبِحَارُ فُجِّرَتْ

Transliteration wa-idhā l-biḥāru fujjirat

Yoruba àti nígbà tí àwọn ibúdò bá ṣàn jára wọn,

Verse 4

وَإِذَا ٱلْقُبُورُ بُعْثِرَتْ

Transliteration wa-idhā l-qubūru buʿ'thirat

Yoruba àti (nígbà tí A bá ta ilẹ̀ sókè), tí A sì mú àwọn òkú jáde (láàyè) láti inú àwọn sàréè,

Verse 5

عَلِمَتْ نَفْسٌ مَّا قَدَّمَتْ وَأَخَّرَتْ

Transliteration ʿalimat nafsun mā qaddamat wa-akharat

Yoruba (nígbà náà ni) ẹ̀mí kọ̀ọ̀kan yóò mọ ohun tí ó tì síwájú (nínú iṣẹ́ rẹ̀) àti ohun tí ó fi sẹ́yìn (nínú orípa iṣẹ́ rẹ̀).

Verse 6

يَـٰٓأَيُّهَا ٱلْإِنسَـٰنُ مَا غَرَّكَ بِرَبِّكَ ٱلْكَرِيمِ

Transliteration yāayyuhā l-insānu mā gharraka birabbika l-karīmi

Yoruba Ìwọ ènìyàn, kí ni ó tàn ọ́ jẹ nípa Olúwa rẹ, Alápọ̀n-ọ́nlé,

Verse 7

ٱلَّذِى خَلَقَكَ فَسَوَّىٰكَ فَعَدَلَكَ

Transliteration alladhī khalaqaka fasawwāka faʿadalaka

Yoruba Ẹni t’Ó ṣẹ̀dá rẹ? Ó ṣẹ̀dá rẹ̀ ní pípé. Ó sì mú ọ dọ́gba jalẹ̀ léèyàn.

Verse 8

فِىٓ أَىِّ صُورَةٍ مَّا شَآءَ رَكَّبَكَ

Transliteration fī ayyi ṣūratin mā shāa rakkabaka

Yoruba Ó to ẹ̀yà ara rẹ papọ̀ sínú èyíkéyìí àwòrán tí Ó fẹ́.

Verse 9

كَلَّا بَلْ تُكَذِّبُونَ بِٱلدِّينِ

Transliteration kallā bal tukadhibūna bil-dīni

Yoruba Rárá! Bí kò ṣe pé ẹ̀ ń pe Ọjọ́ ẹ̀san ní irọ́.

Verse 10

وَإِنَّ عَلَيْكُمْ لَحَـٰفِظِينَ

Transliteration wa-inna ʿalaykum laḥāfiẓīna

Yoruba Dájúdájú àwọn ẹ̀ṣọ́ sì wà ní ọ̀dọ̀ yín.

Verse 11

كِرَامًا كَـٰتِبِينَ

Transliteration kirāman kātibīna

Yoruba (Wọ́n jẹ́) alápọ̀n-ọ́nlé, òǹkọ̀wé-iṣẹ́ ẹ̀dá.

Verse 12

يَعْلَمُونَ مَا تَفْعَلُونَ

Transliteration yaʿlamūna mā tafʿalūna

Yoruba Wọ́n mọ ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.

Verse 13

إِنَّ ٱلْأَبْرَارَ لَفِى نَعِيمٍ

Transliteration inna l-abrāra lafī naʿīmin

Yoruba Dájúdájú àwọn ẹni rere yóò kúkú wà nínú ìgbádùn.

Verse 14

وَإِنَّ ٱلْفُجَّارَ لَفِى جَحِيمٍ

Transliteration wa-inna l-fujāra lafī jaḥīmin

Yoruba Dájúdájú àwọn ẹni ibi yó sì kúkú wà nínú iná Jẹhīm.

Verse 15

يَصْلَوْنَهَا يَوْمَ ٱلدِّينِ

Transliteration yaṣlawnahā yawma l-dīni

Yoruba Wọn yóò wọ inú rẹ̀ ní Ọjọ́ ẹ̀san.

Verse 16

وَمَا هُمْ عَنْهَا بِغَآئِبِينَ

Transliteration wamā hum ʿanhā bighāibīna

Yoruba Wọn kò sì níí kúrò nínú rẹ̀.

Verse 17

وَمَآ أَدْرَىٰكَ مَا يَوْمُ ٱلدِّينِ

Transliteration wamā adrāka mā yawmu l-dīni

Yoruba Kí sì ni ó mú ọ mọ ohun tó ń jẹ́ Ọjọ́ ẹ̀san?

Verse 18

ثُمَّ مَآ أَدْرَىٰكَ مَا يَوْمُ ٱلدِّينِ

Transliteration thumma mā adrāka mā yawmu l-dīni

Yoruba Lẹ́yìn náà, kí ni ó mú ọ mọ ohun tó ń jẹ́ Ọjọ́ ẹ̀san?

Verse 19

يَوْمَ لَا تَمْلِكُ نَفْسٌ لِّنَفْسٍ شَيْـًٔا ۖ وَٱلْأَمْرُ يَوْمَئِذٍ لِّلَّهِ

Transliteration yawma lā tamliku nafsun linafsin shayan wal-amru yawma-idhin lillahi

Yoruba (Ọjọ́ ẹ̀san ni) ọjọ́ tí ẹ̀mí kan kò níí kápá kiní kan fún ẹ̀mí kan. Gbogbo àṣẹ ọjọ́ yẹn sì ń jẹ́ ti Allāhu.

Read Surah Al-Infitar in another language

All languages

All 114 surahs in Yoruba: the Qur’an in Yoruba.

Learn it in MyDugsi

Yoruba translation: Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni, from Quran.com. Transliteration: Quran.com. Recitation: Mishary Alafasy, from EveryAyah.com. MyDugsi is a learning aid, not a replacement for a qualified teacher.