MyDugsiStart learning

Surah Ar-Rum in Yoruba: translation and audio

Surah 30 · الروم · The Romans · 60 verses

Surah Ar-Rum verse by verse: the Arabic with a recitation you can repeat, the transliteration, and the Yoruba translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni. For the meaning of every word, see Surah Ar-Rum word by word in English.

Verse 1

الٓمٓ

Transliteration alif-lam-meem

Yoruba ’Alif lām mīm. (Allāhu ló mọ ohun tí Ó gbàlérò pẹ̀lú àwọn háràfí náà.)1

Verse 2

غُلِبَتِ ٱلرُّومُ

Transliteration ghulibati l-rūmu

Yoruba Wọ́nṣẹ́gun Rōmu

Verse 3

فِىٓ أَدْنَى ٱلْأَرْضِ وَهُم مِّنۢ بَعْدِ غَلَبِهِمْ سَيَغْلِبُونَ

Transliteration fī adnā l-arḍi wahum min baʿdi ghalabihim sayaghlibūna

Yoruba ní àwọn ilẹ̀ tó wà nítòsí (erékùsù Lárúbáwá).Lẹ́yìn ìṣẹ́gun wọn, àwọn náà máa ṣẹ́gun wọn

Verse 4

فِى بِضْعِ سِنِينَ ۗ لِلَّهِ ٱلْأَمْرُ مِن قَبْلُ وَمِنۢ بَعْدُ ۚ وَيَوْمَئِذٍ يَفْرَحُ ٱلْمُؤْمِنُونَ

Transliteration fī biḍ'ʿi sinīna lillahi l-amru min qablu wamin baʿdu wayawma-idhin yafraḥu l-mu'minūna

Yoruba ní ọdún díẹ̀ (sí ìgbà náà). Ti Allāhu ni àṣẹ ní ìṣáájú àti ní ìkẹ́yìn. Ní ọjọ́ yẹn, àwọn onígbàgbọ́ òdodo máa dunnú

Verse 5

بِنَصْرِ ٱللَّهِ ۚ يَنصُرُ مَن يَشَآءُ ۖ وَهُوَ ٱلْعَزِيزُ ٱلرَّحِيمُ

Transliteration binaṣri l-lahi yanṣuru man yashāu wahuwa l-ʿazīzu l-raḥīmu

Yoruba sí àrànṣe Allāhu. Ó ń ṣàrànṣe fún ẹni tí Ó bá fẹ́. Òun sì ni Alágbára, Àṣàkẹ́-ọ̀run.

Verse 6

وَعْدَ ٱللَّهِ ۖ لَا يُخْلِفُ ٱللَّهُ وَعْدَهُۥ وَلَـٰكِنَّ أَكْثَرَ ٱلنَّاسِ لَا يَعْلَمُونَ

Transliteration waʿda l-lahi lā yukh'lifu l-lahu waʿdahu walākinna akthara l-nāsi lā yaʿlamūna

Yoruba (Èyí jẹ́) àdéhùn Allāhu. Allāhu kò sì níí yapa àdéhùn Rẹ̀, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ àwọn ènìyàn kò mọ̀.

Verse 7

يَعْلَمُونَ ظَـٰهِرًا مِّنَ ٱلْحَيَوٰةِ ٱلدُّنْيَا وَهُمْ عَنِ ٱلْـَٔاخِرَةِ هُمْ غَـٰفِلُونَ

Transliteration yaʿlamūna ẓāhiran mina l-ḥayati l-dun'yā wahum ʿani l-ākhirati hum ghāfilūna

Yoruba Wọ́n nímọ̀ nípa gban̄gba nínú ọ̀rọ̀ ìṣẹ̀mí ayé (yìí). Afọ́nú-fọ́ra sì ni wọ́n nípa Ọjọ́ Ìkẹ́yìn.

Verse 8

أَوَلَمْ يَتَفَكَّرُوا۟ فِىٓ أَنفُسِهِم ۗ مَّا خَلَقَ ٱللَّهُ ٱلسَّمَـٰوَٰتِ وَٱلْأَرْضَ وَمَا بَيْنَهُمَآ إِلَّا بِٱلْحَقِّ وَأَجَلٍ مُّسَمًّى ۗ وَإِنَّ كَثِيرًا مِّنَ ٱلنَّاسِ بِلِقَآئِ رَبِّهِمْ لَكَـٰفِرُونَ

Transliteration awalam yatafakkarū fī anfusihim mā khalaqa l-lahu l-samāwāti wal-arḍa wamā baynahumā illā bil-ḥaqi wa-ajalin musamman wa-inna kathīran mina l-nāsi biliqāi rabbihim lakāfirūna

Yoruba Ṣé wọn kò ronú nípa ọ̀rọ̀ ara wọn ni? Allāhu kò ṣẹ̀dá àwọn sánmọ̀, ilẹ̀ àti n̄ǹkan tó wà láààrin àwọn méjèèjì bí kò ṣe pẹ̀lú òdodo àti fún gbèdéke àkókò kan. Dájúdájú ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ nínú àwọn ènìyàn mà ni aláìgbàgbọ́ nínú ìpàdé Olúwa wọn.

Verse 9

أَوَلَمْ يَسِيرُوا۟ فِى ٱلْأَرْضِ فَيَنظُرُوا۟ كَيْفَ كَانَ عَـٰقِبَةُ ٱلَّذِينَ مِن قَبْلِهِمْ ۚ كَانُوٓا۟ أَشَدَّ مِنْهُمْ قُوَّةً وَأَثَارُوا۟ ٱلْأَرْضَ وَعَمَرُوهَآ أَكْثَرَ مِمَّا عَمَرُوهَا وَجَآءَتْهُمْ رُسُلُهُم بِٱلْبَيِّنَـٰتِ ۖ فَمَا كَانَ ٱللَّهُ لِيَظْلِمَهُمْ وَلَـٰكِن كَانُوٓا۟ أَنفُسَهُمْ يَظْلِمُونَ

Transliteration awalam yasīrū fī l-arḍi fayanẓurū kayfa kāna ʿāqibatu alladhīna min qablihim kānū ashadda min'hum quwwatan wa-athārū l-arḍa waʿamarūhā akthara mimmā ʿamarūhā wajāathum rusuluhum bil-bayināti famā kāna l-lahu liyaẓlimahum walākin kānū anfusahum yaẓlimūna

Yoruba Ṣé wọn kò rìn kiri lórí ilẹ̀ kí wọ́n wo bí ìkángun àwọn tó ṣíwájú wọn ṣe rí? Wọ́n ní agbára jù wọ́n lọ. Wọ́n fi ilẹ̀ dáko. Wọ́n sì lo ilẹ̀ fún ohun tí ó pọ̀ ju bí (àwọn ará Mọkkah) ṣe lò ó. Àwọn Òjíṣẹ́ wọn sì mú àwọn ẹ̀rí tó yanjú wá bá wọn. Nítorí náà, Allāhu kò ṣàbòsí sí wọn, ṣùgbọ́n ẹ̀mí ara wọn ni wọ́n ń ṣàbòsí sí.

Verse 10

ثُمَّ كَانَ عَـٰقِبَةَ ٱلَّذِينَ أَسَـٰٓـُٔوا۟ ٱلسُّوٓأَىٰٓ أَن كَذَّبُوا۟ بِـَٔايَـٰتِ ٱللَّهِ وَكَانُوا۟ بِهَا يَسْتَهْزِءُونَ

Transliteration thumma kāna ʿāqibata alladhīna asāū l-sūā an kadhabū biāyāti l-lahi wakānū bihā yastahziūna

Yoruba Lẹ́yìn náà, aburú jẹ́ àtubọ̀tán àwọn tó ṣaburú nítorí pé, wọ́n pe àwọn āyah Allāhu ní irọ́. Wọ́n sì ń fi ṣe yẹ̀yẹ́.

Verse 11

ٱللَّهُ يَبْدَؤُا۟ ٱلْخَلْقَ ثُمَّ يُعِيدُهُۥ ثُمَّ إِلَيْهِ تُرْجَعُونَ

Transliteration al-lahu yabda-u l-khalqa thumma yuʿīduhu thumma ilayhi tur'jaʿūna

Yoruba Allāhu ń pilẹ̀ ẹ̀dá dídá. Lẹ́yìn náà, O máa dá a padà (sípò alààyè). Lẹ́yìn náà, ọ̀dọ̀ Rẹ̀ ni wọn yóò da yín padà sí.

Verse 12

وَيَوْمَ تَقُومُ ٱلسَّاعَةُ يُبْلِسُ ٱلْمُجْرِمُونَ

Transliteration wayawma taqūmu l-sāʿatu yub'lisu l-muj'rimūna

Yoruba Ní ọjọ́ tí Àkókò náà máa ṣẹlẹ̀, àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ yó sọ̀rètí nù.

Verse 13

وَلَمْ يَكُن لَّهُم مِّن شُرَكَآئِهِمْ شُفَعَـٰٓؤُا۟ وَكَانُوا۟ بِشُرَكَآئِهِمْ كَـٰفِرِينَ

Transliteration walam yakun lahum min shurakāihim shufaʿāu wakānū bishurakāihim kāfirīna

Yoruba Àti pé kò níí sí àwọn olùṣìpẹ̀ fún wọn nínú àwọn òrìṣà wọn. Wọ́n sì máa jẹ́ alátakò òrìṣà wọn.

Verse 14

وَيَوْمَ تَقُومُ ٱلسَّاعَةُ يَوْمَئِذٍ يَتَفَرَّقُونَ

Transliteration wayawma taqūmu l-sāʿatu yawma-idhin yatafarraqūna

Yoruba Ní ọjọ́ tí Àkókò náà máa ṣẹlẹ̀, ní ọjọ́ yẹn ni wọn yóò pínyà sí ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀.

Verse 15

فَأَمَّا ٱلَّذِينَ ءَامَنُوا۟ وَعَمِلُوا۟ ٱلصَّـٰلِحَـٰتِ فَهُمْ فِى رَوْضَةٍ يُحْبَرُونَ

Transliteration fa-ammā alladhīna āmanū waʿamilū l-ṣāliḥāti fahum fī rawḍatin yuḥ'barūna

Yoruba Ní ti àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe iṣẹ́ rere, wọn yóò wà ní àbàtà Ọgbà Ìdẹ̀ra,tí wọn yó sì máa dùn wọ́n nínú.

Verse 16

وَأَمَّا ٱلَّذِينَ كَفَرُوا۟ وَكَذَّبُوا۟ بِـَٔايَـٰتِنَا وَلِقَآئِ ٱلْـَٔاخِرَةِ فَأُو۟لَـٰٓئِكَ فِى ٱلْعَذَابِ مُحْضَرُونَ

Transliteration wa-ammā alladhīna kafarū wakadhabū biāyātinā waliqāi l-ākhirati fa-ulāika fī l-ʿadhābi muḥ'ḍarūna

Yoruba Ní ti àwọn tó ṣàì gbàgbọ́, tí wọ́n sì pé àwọn āyah Wa àti ìpàdé Ọjọ́ Ìkẹ́yìn ní irọ́, àwọn wọ̀nyẹn ni (àwọn mọlāika) máa kó wá sínú Iná.

Verse 17

فَسُبْحَـٰنَ ٱللَّهِ حِينَ تُمْسُونَ وَحِينَ تُصْبِحُونَ

Transliteration fasub'ḥāna l-lahi ḥīna tum'sūna waḥīna tuṣ'biḥūna

Yoruba Nítorí náà, ẹ ṣe àfọ̀mọ́ fún Allāhu nígbà tí ẹ bá wà ní ìrọ̀lẹ́ àti nígbà tí ẹ bá wà ní òwúrọ̀.

Verse 18

وَلَهُ ٱلْحَمْدُ فِى ٱلسَّمَـٰوَٰتِ وَٱلْأَرْضِ وَعَشِيًّا وَحِينَ تُظْهِرُونَ

Transliteration walahu l-ḥamdu fī l-samāwāti wal-arḍi waʿashiyyan waḥīna tuẓ'hirūna

Yoruba TiRẹ̀ sì ni ọpẹ́ nínú àwọn sánmọ̀ àti lórí ilẹ̀ ní àṣálẹ́ àti nígbà tí ẹ bá wà ní ọ̀sán.

Verse 19

يُخْرِجُ ٱلْحَىَّ مِنَ ٱلْمَيِّتِ وَيُخْرِجُ ٱلْمَيِّتَ مِنَ ٱلْحَىِّ وَيُحْىِ ٱلْأَرْضَ بَعْدَ مَوْتِهَا ۚ وَكَذَٰلِكَ تُخْرَجُونَ

Transliteration yukh'riju l-ḥaya mina l-mayiti wayukh'riju l-mayita mina l-ḥayi wayuḥ'yī l-arḍa baʿda mawtihā wakadhālika tukh'rajūna

Yoruba (Allāhu) ń yọ alààyè jáde láti ara òkú. Ó ń yọ òkú jáde láti ara alààyè. Ó ń ta ilẹ̀ jí lẹ́yìn tí ilẹ̀ ti kú. Báyẹn ni A óò ṣe mu ẹ̀yin náà jáde.

Verse 20

وَمِنْ ءَايَـٰتِهِۦٓ أَنْ خَلَقَكُم مِّن تُرَابٍ ثُمَّ إِذَآ أَنتُم بَشَرٌ تَنتَشِرُونَ

Transliteration wamin āyātihi an khalaqakum min turābin thumma idhā antum basharun tantashirūna

Yoruba Ó wà nínú àwọn àmì Rẹ̀ pé, Ó ṣẹ̀dá yín láti ara erùpẹ̀. Lẹ́yìn náà, nígbà náà ẹ̀yin di abara tí ẹ̀ ń fọ́nká (lórí ilẹ̀ ayé).

Verse 21

وَمِنْ ءَايَـٰتِهِۦٓ أَنْ خَلَقَ لَكُم مِّنْ أَنفُسِكُمْ أَزْوَٰجًا لِّتَسْكُنُوٓا۟ إِلَيْهَا وَجَعَلَ بَيْنَكُم مَّوَدَّةً وَرَحْمَةً ۚ إِنَّ فِى ذَٰلِكَ لَـَٔايَـٰتٍ لِّقَوْمٍ يَتَفَكَّرُونَ

Transliteration wamin āyātihi an khalaqa lakum min anfusikum azwājan litaskunū ilayhā wajaʿala baynakum mawaddatan waraḥmatan inna fī dhālika laāyātin liqawmin yatafakkarūna

Yoruba Ó wà nínú àwọn àmì Rẹ̀ pé, Ó ṣẹ̀dá àwọn aya fún yín láti ara yín nítorí kí ẹ lè rí ìfàyàbalẹ̀ lọ́dọ̀ wọn. Ó sì fi ìfẹ́ àti ìkẹ́ sí ààrin yín. Dájúdájú àwọn àmì wà nínú ìyẹn fún ìjọ tó láròjinlẹ̀.

Verse 22

وَمِنْ ءَايَـٰتِهِۦ خَلْقُ ٱلسَّمَـٰوَٰتِ وَٱلْأَرْضِ وَٱخْتِلَـٰفُ أَلْسِنَتِكُمْ وَأَلْوَٰنِكُمْ ۚ إِنَّ فِى ذَٰلِكَ لَـَٔايَـٰتٍ لِّلْعَـٰلِمِينَ

Transliteration wamin āyātihi khalqu l-samāwāti wal-arḍi wa-ikh'tilāfu alsinatikum wa-alwānikum inna fī dhālika laāyātin lil'ʿālimīna

Yoruba Ó wà nínú àwọn àmì Rẹ̀, dídá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ àti ọ̀kan-ò-jọ̀kan àwọn èdè yín àti àwọn àwọ̀ ara yín. Dájúdájú àwọn àmì wà nínú ìyẹn fún àwọn onímọ̀.

Verse 23

وَمِنْ ءَايَـٰتِهِۦ مَنَامُكُم بِٱلَّيْلِ وَٱلنَّهَارِ وَٱبْتِغَآؤُكُم مِّن فَضْلِهِۦٓ ۚ إِنَّ فِى ذَٰلِكَ لَـَٔايَـٰتٍ لِّقَوْمٍ يَسْمَعُونَ

Transliteration wamin āyātihi manāmukum bi-al-layli wal-nahāri wa-ib'tighāukum min faḍlihi inna fī dhālika laāyātin liqawmin yasmaʿūna

Yoruba Nínú àwọn àmì Rẹ̀ ni oorun yín ní alẹ́ àti ní ọ̀sán àti wíwá tí ẹ̀ ń wá nínú oore Rẹ̀ (fún ìjẹ-ìmu). Dájúdájú àwọn àmì wà nínú ìyẹn fún ìjọ tó ń gbọ́rọ̀.

Verse 24

وَمِنْ ءَايَـٰتِهِۦ يُرِيكُمُ ٱلْبَرْقَ خَوْفًا وَطَمَعًا وَيُنَزِّلُ مِنَ ٱلسَّمَآءِ مَآءً فَيُحْىِۦ بِهِ ٱلْأَرْضَ بَعْدَ مَوْتِهَآ ۚ إِنَّ فِى ذَٰلِكَ لَـَٔايَـٰتٍ لِّقَوْمٍ يَعْقِلُونَ

Transliteration wamin āyātihi yurīkumu l-barqa khawfan waṭamaʿan wayunazzilu mina l-samāi māan fayuḥ'yī bihi l-arḍa baʿda mawtihā inna fī dhālika laāyātin liqawmin yaʿqilūna

Yoruba Nínú àwọn àmì Rẹ̀ tún ni fífi mọ̀nàmọ́ná hàn yín ní ti ẹ̀rù àti ìrètí. Ó sì ń sọ omi kalẹ̀ láti sánmọ̀. Ó ń fi ta ilẹ̀ jí lẹ́yìn tí ilẹ̀ ti kú. Dájúdájú àwọn àmì wà nínú ìyẹn fún ìjọ tó ń ṣe làákàyè.

Verse 25

وَمِنْ ءَايَـٰتِهِۦٓ أَن تَقُومَ ٱلسَّمَآءُ وَٱلْأَرْضُ بِأَمْرِهِۦ ۚ ثُمَّ إِذَا دَعَاكُمْ دَعْوَةً مِّنَ ٱلْأَرْضِ إِذَآ أَنتُمْ تَخْرُجُونَ

Transliteration wamin āyātihi an taqūma l-samāu wal-arḍu bi-amrihi thumma idhā daʿākum daʿwatan mina l-arḍi idhā antum takhrujūna

Yoruba Àti pé nínú àwọn àmì Rẹ̀ ni pé sánmọ̀ àti ilẹ̀ dúró pẹ̀lú àṣẹ Rẹ̀. Lẹ́yìn náà, nígbà tí Ó bá pè yín ní ìpè kan nígbà náà ni ẹ̀yin yóò máa jáde láti inú ilẹ̀.

Verse 26

وَلَهُۥ مَن فِى ٱلسَّمَـٰوَٰتِ وَٱلْأَرْضِ ۖ كُلٌّ لَّهُۥ قَـٰنِتُونَ

Transliteration walahu man fī l-samāwāti wal-arḍi kullun lahu qānitūna

Yoruba TiRẹ̀ ni àwọn tó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Ẹnì kọ̀ọ̀kan ni olùtẹ̀lé-àṣẹ Rẹ̀.1

Verse 27

وَهُوَ ٱلَّذِى يَبْدَؤُا۟ ٱلْخَلْقَ ثُمَّ يُعِيدُهُۥ وَهُوَ أَهْوَنُ عَلَيْهِ ۚ وَلَهُ ٱلْمَثَلُ ٱلْأَعْلَىٰ فِى ٱلسَّمَـٰوَٰتِ وَٱلْأَرْضِ ۚ وَهُوَ ٱلْعَزِيزُ ٱلْحَكِيمُ

Transliteration wahuwa alladhī yabda-u l-khalqa thumma yuʿīduhu wahuwa ahwanu ʿalayhi walahu l-mathalu l-aʿlā fī l-samāwāti wal-arḍi wahuwa l-ʿazīzu l-ḥakīmu

Yoruba Òun ni Ẹni tí Ó ń bẹ̀rẹ̀ ẹ̀dá dídá. Lẹ́yìn náà, Ó máa dá a padà (sípò alààyè fún àjíǹde). Ó sì rọrùn jùlọ fún Un (láti ṣe bẹ́ẹ̀). TiRẹ̀ ni ìròyìn tó ga jùlọ nínú àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀.Òun sì ni Alágbára, Ọlọ́gbọ́n.

Verse 28

ضَرَبَ لَكُم مَّثَلًا مِّنْ أَنفُسِكُمْ ۖ هَل لَّكُم مِّن مَّا مَلَكَتْ أَيْمَـٰنُكُم مِّن شُرَكَآءَ فِى مَا رَزَقْنَـٰكُمْ فَأَنتُمْ فِيهِ سَوَآءٌ تَخَافُونَهُمْ كَخِيفَتِكُمْ أَنفُسَكُمْ ۚ كَذَٰلِكَ نُفَصِّلُ ٱلْـَٔايَـٰتِ لِقَوْمٍ يَعْقِلُونَ

Transliteration ḍaraba lakum mathalan min anfusikum hal lakum min mā malakat aymānukum min shurakāa fī mā razaqnākum fa-antum fīhi sawāon takhāfūnahum kakhīfatikum anfusakum kadhālika nufaṣṣilu l-āyāti liqawmin yaʿqilūna

Yoruba (Allāhu) ṣàkàwé kan fún yín nípa ara yín. Ǹjẹ́ ẹ ní akẹgbẹ́ nínú àwọn ẹrú yín lórí ohun tí A fún yín ní arísìkí, tí ẹ jọ máa pín (dúkìá náà) ní dọ́gban̄dọ́gba, tí ẹ ó sì máa páyà wọn gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe ń páyà ẹ̀yin náà? Báyẹn ni A ṣe ń ṣ’àlàyé àwọn āyah fún ìjọ tó ń ṣe làákàyè.1

Verse 29

بَلِ ٱتَّبَعَ ٱلَّذِينَ ظَلَمُوٓا۟ أَهْوَآءَهُم بِغَيْرِ عِلْمٍ ۖ فَمَن يَهْدِى مَنْ أَضَلَّ ٱللَّهُ ۖ وَمَا لَهُم مِّن نَّـٰصِرِينَ

Transliteration bali ittabaʿa alladhīna ẓalamū ahwāahum bighayri ʿil'min faman yahdī man aḍalla l-lahu wamā lahum min nāṣirīna

Yoruba Ńṣe ni àwọn tó ṣàbòsí tẹ̀lé ìfẹ́-inú wọn láì sí ìmọ̀ kan (fún wọn). Ta sì ni ó lè fi ọ̀nà mọ ẹni tí Allāhu bá ṣì lọ́nà? Kò sì níí sí àwọn alárànṣe fún wọn.

Verse 30

فَأَقِمْ وَجْهَكَ لِلدِّينِ حَنِيفًا ۚ فِطْرَتَ ٱللَّهِ ٱلَّتِى فَطَرَ ٱلنَّاسَ عَلَيْهَا ۚ لَا تَبْدِيلَ لِخَلْقِ ٱللَّهِ ۚ ذَٰلِكَ ٱلدِّينُ ٱلْقَيِّمُ وَلَـٰكِنَّ أَكْثَرَ ٱلنَّاسِ لَا يَعْلَمُونَ

Transliteration fa-aqim wajhaka lilddīni ḥanīfan fiṭ'rata l-lahi allatī faṭara l-nāsa ʿalayhā lā tabdīla likhalqi l-lahi dhālika l-dīnu l-qayimu walākinna akthara l-nāsi lā yaʿlamūna

Yoruba Nítorí náà, dojú rẹ kọ ẹ̀sìn náà, (kí o jẹ́) olùdúró-déédé-nínú-ẹ̀sìn Islām, ẹ̀sìn àdámọ́ Allāhu èyí tí Ó dá mọ́ àwọn ènìyàn. Kò sí ìyípadà fún ẹ̀sìn Allāhu.(ìyẹn ni pé, ẹ kò gbọ́dọ̀ yí ẹ̀sìn Allāhu padà.)2 Ìyẹn ni ẹ̀sìn tó fẹsẹ̀rinlẹ̀, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ àwọn ènìyàn kò mọ̀.3

Verse 31

۞ مُنِيبِينَ إِلَيْهِ وَٱتَّقُوهُ وَأَقِيمُوا۟ ٱلصَّلَوٰةَ وَلَا تَكُونُوا۟ مِنَ ٱلْمُشْرِكِينَ

Transliteration munībīna ilayhi wa-ittaqūhu wa-aqīmū l-ṣalata walā takūnū mina l-mush'rikīna

Yoruba (Ẹ jẹ́) olùṣẹ́rí padà sí ọ̀dọ̀ Allāhu (nípa ìronúpìwàdà). Ẹ páyà Rẹ̀. Ẹ kí ìrun. Ẹ má ṣe wà nínú àwọn ọ̀ṣẹbọ.

Verse 32

مِنَ ٱلَّذِينَ فَرَّقُوا۟ دِينَهُمْ وَكَانُوا۟ شِيَعًا ۖ كُلُّ حِزْبٍۭ بِمَا لَدَيْهِمْ فَرِحُونَ

Transliteration mina alladhīna farraqū dīnahum wakānū shiyaʿan kullu ḥiz'bin bimā ladayhim fariḥūna

Yoruba (Ẹ má ṣe wà) nínú àwọn tó dá ẹ̀sìn wọn sí kélekèle, tí wọ́n sì di ìjọ-ìjọ. Ìjọ kọ̀ọ̀kan sì ń yọ̀ sí ohun tí ó wà lọ́dọ̀ wọn.

Verse 33

وَإِذَا مَسَّ ٱلنَّاسَ ضُرٌّ دَعَوْا۟ رَبَّهُم مُّنِيبِينَ إِلَيْهِ ثُمَّ إِذَآ أَذَاقَهُم مِّنْهُ رَحْمَةً إِذَا فَرِيقٌ مِّنْهُم بِرَبِّهِمْ يُشْرِكُونَ

Transliteration wa-idhā massa l-nāsa ḍurrun daʿaw rabbahum munībīna ilayhi thumma idhā adhāqahum min'hu raḥmatan idhā farīqun min'hum birabbihim yush'rikūna

Yoruba Nígbà tí ìnira kan bá fọwọ́ ba ènìyàn, wọn yóò pe Olúwa wọn, tí wọn yóò máa ṣẹ́rí padà sọ́dọ̀ Rẹ̀. Lẹ́yìn náà, nígbà tí (Allāhu) bá fún wọn ní ìkẹ́ kan tọ́ wò láti ọ̀dọ̀ Rẹ̀, nígbà náà ni igun kan nínú wọn yóò máa ṣẹbọ sí Olúwa wọn

Verse 34

لِيَكْفُرُوا۟ بِمَآ ءَاتَيْنَـٰهُمْ ۚ فَتَمَتَّعُوا۟ فَسَوْفَ تَعْلَمُونَ

Transliteration liyakfurū bimā ātaynāhum fatamattaʿū fasawfa taʿlamūna

Yoruba nítorí kí wọ́n lè ṣàì moore sí ohun tí (Allāhu) fún wọn. Ẹ máa jayé lọ. Nítorí náà, láìpẹ́ ẹ máa mọ̀.

Verse 35

أَمْ أَنزَلْنَا عَلَيْهِمْ سُلْطَـٰنًا فَهُوَ يَتَكَلَّمُ بِمَا كَانُوا۟ بِهِۦ يُشْرِكُونَ

Transliteration am anzalnā ʿalayhim sul'ṭānan fahuwa yatakallamu bimā kānū bihi yush'rikūna

Yoruba Tàbí A sọ ẹ̀rí kan kalẹ̀ fún wọn, tó ń sọ̀rọ̀ nípa n̄ǹkan tí wọ́n ń sọ di akẹgbẹ́ Rẹ̀?

Verse 36

وَإِذَآ أَذَقْنَا ٱلنَّاسَ رَحْمَةً فَرِحُوا۟ بِهَا ۖ وَإِن تُصِبْهُمْ سَيِّئَةٌۢ بِمَا قَدَّمَتْ أَيْدِيهِمْ إِذَا هُمْ يَقْنَطُونَ

Transliteration wa-idhā adhaqnā l-nāsa raḥmatan fariḥū bihā wa-in tuṣib'hum sayyi-atun bimā qaddamat aydīhim idhā hum yaqnaṭūna

Yoruba Nígbà tí A bá fi ìkẹ́ kan tọ́ ènìyàn lẹ́nu wò, wọn yóò dunnú sí i. Tí aburú kan bá sì kàn wọ́n nípa ohun tí ọwọ́ wọn tì síwájú, nígbà náà ni wọn yóò sọ̀rètí nù.

Verse 37

أَوَلَمْ يَرَوْا۟ أَنَّ ٱللَّهَ يَبْسُطُ ٱلرِّزْقَ لِمَن يَشَآءُ وَيَقْدِرُ ۚ إِنَّ فِى ذَٰلِكَ لَـَٔايَـٰتٍ لِّقَوْمٍ يُؤْمِنُونَ

Transliteration awalam yaraw anna l-laha yabsuṭu l-riz'qa liman yashāu wayaqdiru inna fī dhālika laāyātin liqawmin yu'minūna

Yoruba Ṣé wọn kò wòye pé dájúdájú Allāhu l’Ó ń tẹ́ ọrọ̀ sílẹ̀ fún ẹni tí Ó bá fẹ́, (Ó sì ń) díwọ̀n rẹ̀ (fún ẹni tí Ó bá fẹ́)? Dájúdájú àwọn àmì wà nínú ìyẹn fún ìjọ tó gbàgbọ́.

Verse 38

فَـَٔاتِ ذَا ٱلْقُرْبَىٰ حَقَّهُۥ وَٱلْمِسْكِينَ وَٱبْنَ ٱلسَّبِيلِ ۚ ذَٰلِكَ خَيْرٌ لِّلَّذِينَ يُرِيدُونَ وَجْهَ ٱللَّهِ ۖ وَأُو۟لَـٰٓئِكَ هُمُ ٱلْمُفْلِحُونَ

Transliteration faāti dhā l-qur'bā ḥaqqahu wal-mis'kīna wa-ib'na l-sabīli dhālika khayrun lilladhīna yurīdūna wajha l-lahi wa-ulāika humu l-muf'liḥūna

Yoruba Nítorí náà, fún ẹbí ni ẹ̀tọ́ rẹ̀. (Fún) mẹ̀kúnnù àti onírìn-àjò (tí agara dá ní n̄ǹkan). Ìyẹn lóore jùlọ fún àwọn tó ń fẹ́ Ojú rere Allāhu. Àwọn wọ̀nyẹn, àwọn sì ni olùjèrè.

Verse 39

وَمَآ ءَاتَيْتُم مِّن رِّبًا لِّيَرْبُوَا۟ فِىٓ أَمْوَٰلِ ٱلنَّاسِ فَلَا يَرْبُوا۟ عِندَ ٱللَّهِ ۖ وَمَآ ءَاتَيْتُم مِّن زَكَوٰةٍ تُرِيدُونَ وَجْهَ ٱللَّهِ فَأُو۟لَـٰٓئِكَ هُمُ ٱلْمُضْعِفُونَ

Transliteration wamā ātaytum min riban liyarbuwā fī amwāli l-nāsi falā yarbū ʿinda l-lahi wamā ātaytum min zakatin turīdūna wajha l-lahi fa-ulāika humu l-muḍ'ʿifūna

Yoruba Ohunkóhun tí ẹ bá fún (àwọn ènìyàn) ní ẹ̀yáwó, nítorí kí ó lè di èlé láti ara dúkìá àwọn ènìyàn, kò lè lékún ní ọ̀dọ̀ Allāhu. Ohunkóhun tí ẹ bá sì (fún àwọn ènìyàn) ní Zakāh, tí ẹ̀ ń fẹ́ ojú rere Allāhu, àwọn wọ̀nyẹn ni A máa fún ní àdìpèlé ẹ̀san.

Verse 40

ٱللَّهُ ٱلَّذِى خَلَقَكُمْ ثُمَّ رَزَقَكُمْ ثُمَّ يُمِيتُكُمْ ثُمَّ يُحْيِيكُمْ ۖ هَلْ مِن شُرَكَآئِكُم مَّن يَفْعَلُ مِن ذَٰلِكُم مِّن شَىْءٍ ۚ سُبْحَـٰنَهُۥ وَتَعَـٰلَىٰ عَمَّا يُشْرِكُونَ

Transliteration al-lahu alladhī khalaqakum thumma razaqakum thumma yumītukum thumma yuḥ'yīkum hal min shurakāikum man yafʿalu min dhālikum min shayin sub'ḥānahu wataʿālā ʿammā yush'rikūna

Yoruba Allāhu, Ẹni tí Ó ṣẹ̀dá yín, lẹ́yìn náà, Ó fún yín ní arísìkí, lẹ́yìn náà, Ó máa sọ yín di òkú, lẹ́yìn náà, O máa sọ yín di alààyè. Ǹjẹ́ ó wà nínú àwọn òrìṣà yín ẹni tí ó lè ṣe n̄ǹkan kan nínú ìyẹn? Mímọ́ ni fún Un. Ó ga tayọ n̄ǹkan tí wọ́n ń fi ṣẹbọ sí I.

Verse 41

ظَهَرَ ٱلْفَسَادُ فِى ٱلْبَرِّ وَٱلْبَحْرِ بِمَا كَسَبَتْ أَيْدِى ٱلنَّاسِ لِيُذِيقَهُم بَعْضَ ٱلَّذِى عَمِلُوا۟ لَعَلَّهُمْ يَرْجِعُونَ

Transliteration ẓahara l-fasādu fī l-bari wal-baḥri bimā kasabat aydī l-nāsi liyudhīqahum baʿḍa alladhī ʿamilū laʿallahum yarjiʿūna

Yoruba Ìbàjẹ́ hàn lórí ilẹ̀ àti lójú omi nípasẹ̀ ohun tí ọwọ́ àwọn ènìyàn ṣe níṣẹ́ (aburú) nítorí kí (Allāhu) lè fi (ìyà) apá kan èyí tí wọ́n ṣe níṣẹ́ (aburú) tọ́ wọn lẹ́nu wò nítorí kí wọ́n lè ṣẹ́rí padà (níbi aburú).

Verse 42

قُلْ سِيرُوا۟ فِى ٱلْأَرْضِ فَٱنظُرُوا۟ كَيْفَ كَانَ عَـٰقِبَةُ ٱلَّذِينَ مِن قَبْلُ ۚ كَانَ أَكْثَرُهُم مُّشْرِكِينَ

Transliteration qul sīrū fī l-arḍi fa-unẓurū kayfa kāna ʿāqibatu alladhīna min qablu kāna aktharuhum mush'rikīna

Yoruba Sọ pé: “Ẹ rìn lórí ilẹ̀, kí ẹ wo bí àtubọ̀tán àwọn tó ṣíwájú ṣe rí! Ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn ni wọ́n jẹ́ ọ̀ṣẹbọ.”

Verse 43

فَأَقِمْ وَجْهَكَ لِلدِّينِ ٱلْقَيِّمِ مِن قَبْلِ أَن يَأْتِىَ يَوْمٌ لَّا مَرَدَّ لَهُۥ مِنَ ٱللَّهِ ۖ يَوْمَئِذٍ يَصَّدَّعُونَ

Transliteration fa-aqim wajhaka lilddīni l-qayimi min qabli an yatiya yawmun lā maradda lahu mina l-lahi yawma-idhin yaṣṣaddaʿūna

Yoruba Nítorí náà, dojú rẹ kọ ẹ̀sìn tó fẹsẹ̀rinlẹ̀ ṣíwájú kí ọjọ́ kan tó dé, tí kò sí n̄ǹkan tí ó lè yẹ̀ ẹ́ lọ́dọ̀ Allāhu. Ní ọjọ́ yẹn ni àwọn ènìyàn yóò pínyà sí (èrò Ọgbà Ìdẹ̀ra àti èrò Iná).

Verse 44

مَن كَفَرَ فَعَلَيْهِ كُفْرُهُۥ ۖ وَمَنْ عَمِلَ صَـٰلِحًا فَلِأَنفُسِهِمْ يَمْهَدُونَ

Transliteration man kafara faʿalayhi kuf'ruhu waman ʿamila ṣāliḥan fali-anfusihim yamhadūna

Yoruba Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣàì gbàgbọ́, orí ara rẹ̀ ni (ìyà) àìgbàgbọ́ rẹ̀ wà. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì ṣe iṣẹ́ rere, ẹ̀mí ara wọn ni wọ́n ń tẹ́ ìtẹ́ (Ọgbà Ìdẹ̀ra) sílẹ̀ fún

Verse 45

لِيَجْزِىَ ٱلَّذِينَ ءَامَنُوا۟ وَعَمِلُوا۟ ٱلصَّـٰلِحَـٰتِ مِن فَضْلِهِۦٓ ۚ إِنَّهُۥ لَا يُحِبُّ ٱلْكَـٰفِرِينَ

Transliteration liyajziya alladhīna āmanū waʿamilū l-ṣāliḥāti min faḍlihi innahu lā yuḥibbu l-kāfirīna

Yoruba nítorí kí (Allāhu) lè san ẹ̀san rere nínú oore àjùlọ Rẹ̀ fún àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe iṣẹ́ rere. Dájúdájú (Allāhu) kò nífẹ̀ẹ́ àwọn aláìgbàgbọ́.

Verse 46

وَمِنْ ءَايَـٰتِهِۦٓ أَن يُرْسِلَ ٱلرِّيَاحَ مُبَشِّرَٰتٍ وَلِيُذِيقَكُم مِّن رَّحْمَتِهِۦ وَلِتَجْرِىَ ٱلْفُلْكُ بِأَمْرِهِۦ وَلِتَبْتَغُوا۟ مِن فَضْلِهِۦ وَلَعَلَّكُمْ تَشْكُرُونَ

Transliteration wamin āyātihi an yur'sila l-riyāḥa mubashirātin waliyudhīqakum min raḥmatihi walitajriya l-ful'ku bi-amrihi walitabtaghū min faḍlihi walaʿallakum tashkurūna

Yoruba Nínú àwọn àmì Rẹ̀ ni pé, Ó ń rán atẹ́gùn ní ìró ìdùnnú. Àti pé nítorí kí (Allāhu) lè fún yín tọ́ wò nínú ìkẹ́ Rẹ̀; àti nítorí kí ọkọ̀ ojú-omi lè rìn lójú-omi pẹ̀lú àṣẹ Rẹ̀; àti nítorí kí ẹ lè wá nínú oore Rẹ̀; àti nítorí kí ẹ lè dúpẹ́.

Verse 47

وَلَقَدْ أَرْسَلْنَا مِن قَبْلِكَ رُسُلًا إِلَىٰ قَوْمِهِمْ فَجَآءُوهُم بِٱلْبَيِّنَـٰتِ فَٱنتَقَمْنَا مِنَ ٱلَّذِينَ أَجْرَمُوا۟ ۖ وَكَانَ حَقًّا عَلَيْنَا نَصْرُ ٱلْمُؤْمِنِينَ

Transliteration walaqad arsalnā min qablika rusulan ilā qawmihim fajāūhum bil-bayināti fa-intaqamnā mina alladhīna ajramū wakāna ḥaqqan ʿalaynā naṣru l-mu'minīna

Yoruba Dájúdájú A ti rán àwọn Òjíṣẹ́ kan níṣẹ́ ṣíwájú rẹ sí àwọn ìjọ wọn. Wọ́n sì wá bá wọn pẹ̀lú àwọn ẹ̀rí tó yanjú. A sì gbẹ̀san lára àwọn tó dẹ́ṣẹ̀. Ó sì jẹ́ ẹ̀tọ́ fún wa láti ṣe àrànṣe fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo.

Verse 48

ٱللَّهُ ٱلَّذِى يُرْسِلُ ٱلرِّيَـٰحَ فَتُثِيرُ سَحَابًا فَيَبْسُطُهُۥ فِى ٱلسَّمَآءِ كَيْفَ يَشَآءُ وَيَجْعَلُهُۥ كِسَفًا فَتَرَى ٱلْوَدْقَ يَخْرُجُ مِنْ خِلَـٰلِهِۦ ۖ فَإِذَآ أَصَابَ بِهِۦ مَن يَشَآءُ مِنْ عِبَادِهِۦٓ إِذَا هُمْ يَسْتَبْشِرُونَ

Transliteration al-lahu alladhī yur'silu l-riyāḥa fatuthīru saḥāban fayabsuṭuhu fī l-samāi kayfa yashāu wayajʿaluhu kisafan fatarā l-wadqa yakhruju min khilālihi fa-idhā aṣāba bihi man yashāu min ʿibādihi idhā hum yastabshirūna

Yoruba Allāhu ni Ẹni tó ń fi àwọn atẹ́gùn ránṣẹ́. (Atẹ́gùn náà) sì máa gbé ẹ̀ṣújò dìde. (Allāhu) yó sì tẹ́ (ẹ̀ṣújò) sílẹ̀ s’ójú sánmọ̀ bí Ó bá ṣe fẹ́. Ó sì máa dá a kélekèle (sí ojú sánmọ̀). O sì máa rí òjò tí ó ma máa jáde láààrin rẹ̀. Nígbà tí Ó bá sì rọ (òjò náà) fún ẹni tí Ó bá fẹ́ nínú àwọn ẹrúsìn Rẹ̀, nígbà náà wọn yó sì máa dunnú.

Verse 49

وَإِن كَانُوا۟ مِن قَبْلِ أَن يُنَزَّلَ عَلَيْهِم مِّن قَبْلِهِۦ لَمُبْلِسِينَ

Transliteration wa-in kānū min qabli an yunazzala ʿalayhim min qablihi lamub'lisīna

Yoruba Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ṣíwájú kí Ó tó sọ̀ ọ́ kalẹ̀ fún wọn, wọ́n ti sọ̀rètí nù ṣíwájú rẹ̀.

Verse 50

فَٱنظُرْ إِلَىٰٓ ءَاثَـٰرِ رَحْمَتِ ٱللَّهِ كَيْفَ يُحْىِ ٱلْأَرْضَ بَعْدَ مَوْتِهَآ ۚ إِنَّ ذَٰلِكَ لَمُحْىِ ٱلْمَوْتَىٰ ۖ وَهُوَ عَلَىٰ كُلِّ شَىْءٍ قَدِيرٌ

Transliteration fa-unẓur ilā āthāri raḥmati l-lahi kayfa yuḥ'yī l-arḍa baʿda mawtihā inna dhālika lamuḥ'yī l-mawtā wahuwa ʿalā kulli shayin qadīrun

Yoruba Nítorí náà, wòye sí àwọn orípa ìkẹ́ Allāhu, (wo) bí (Allāhu) ṣe ń ta ilẹ̀ jí lẹ́yìn tí ilẹ̀ ti kú. Dájúdájú (Allāhu) yẹn ni Ó kúkú máa sọ àwọn òkú di alààyè. Òun sì ni Alágbára lórí gbogbo n̄ǹkan.

Verse 51

وَلَئِنْ أَرْسَلْنَا رِيحًا فَرَأَوْهُ مُصْفَرًّا لَّظَلُّوا۟ مِنۢ بَعْدِهِۦ يَكْفُرُونَ

Transliteration wala-in arsalnā rīḥan fara-awhu muṣ'farran laẓallū min baʿdihi yakfurūna

Yoruba Dájúdájú tí A bá rán atẹ́gùn kan (sí wọn), kí wọ́n sì rí (n̄ǹkan ọ̀gbìn wọn) ní pípọ́n (jíjóná), dájúdájú wọn yó sì máa ṣàì moore lọ lẹ́yìn rẹ̀.

Verse 52

فَإِنَّكَ لَا تُسْمِعُ ٱلْمَوْتَىٰ وَلَا تُسْمِعُ ٱلصُّمَّ ٱلدُّعَآءَ إِذَا وَلَّوْا۟ مُدْبِرِينَ

Transliteration fa-innaka lā tus'miʿu l-mawtā walā tus'miʿu l-ṣuma l-duʿāa idhā wallaw mud'birīna

Yoruba Dájúdájú ìwọ kọ́ l’o máa mú àwọn òkú gbọ́rọ̀. O ò sì níí mú àwọn adití gbọ́ ìpè nígbà tí wọ́n bá kẹ̀yìn sí ọ, tí wọ́n ń lọ.

Verse 53

وَمَآ أَنتَ بِهَـٰدِ ٱلْعُمْىِ عَن ضَلَـٰلَتِهِمْ ۖ إِن تُسْمِعُ إِلَّا مَن يُؤْمِنُ بِـَٔايَـٰتِنَا فَهُم مُّسْلِمُونَ

Transliteration wamā anta bihādi l-ʿum'yi ʿan ḍalālatihim in tus'miʿu illā man yu'minu biāyātinā fahum mus'limūna

Yoruba Ìwọ kọ́ l’o máa fi ọ̀nà mọ àwọn afọ́jú níbi ìṣìnà wọn. Kò sí ẹni tí o máa mú gbọ́ ọ̀rọ̀ àfi ẹni tí ó bá gba àwọn āyah Wa gbọ́. Àwọn sì ni (mùsùlùmí) olùjupá-jusẹ̀-sílẹ̀ fún Allāhu.1

Verse 54

۞ ٱللَّهُ ٱلَّذِى خَلَقَكُم مِّن ضَعْفٍ ثُمَّ جَعَلَ مِنۢ بَعْدِ ضَعْفٍ قُوَّةً ثُمَّ جَعَلَ مِنۢ بَعْدِ قُوَّةٍ ضَعْفًا وَشَيْبَةً ۚ يَخْلُقُ مَا يَشَآءُ ۖ وَهُوَ ٱلْعَلِيمُ ٱلْقَدِيرُ

Transliteration al-lahu alladhī khalaqakum min ḍaʿfin thumma jaʿala min baʿdi ḍaʿfin quwwatan thumma jaʿala min baʿdi quwwatin ḍaʿfan washaybatan yakhluqu mā yashāu wahuwa l-ʿalīmu l-qadīru

Yoruba Allāhu, Ẹni tí Ó ṣẹ̀dá yín láti (ara n̄ǹkan) lílẹ, lẹ́yìn náà, lẹ́yìn lílẹ Ó fun (yín ní) agbára, lẹ́yìn náà, lẹ́yìn agbára, Ó tún fi lílẹ àti ogbó (si yín lára). Ó ń dá ohunkóhun tí Ó bá fẹ́. Òun sì ni Onímọ̀, Alágbára.

Verse 55

وَيَوْمَ تَقُومُ ٱلسَّاعَةُ يُقْسِمُ ٱلْمُجْرِمُونَ مَا لَبِثُوا۟ غَيْرَ سَاعَةٍ ۚ كَذَٰلِكَ كَانُوا۟ يُؤْفَكُونَ

Transliteration wayawma taqūmu l-sāʿatu yuq'simu l-muj'rimūna mā labithū ghayra sāʿatin kadhālika kānū yu'fakūna

Yoruba Àti pé ní ọjọ́ tí Àkókò náà bá ṣẹlẹ̀ (ìyẹn, ọjọ́ Àjíǹde), àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ yóò máa búra pé àwọn kò gbé (ilé ayé) ju àkókò kan lọ.” Báyẹn ni wọ́n ṣe máa ń ṣẹ́rí wọn kúrò níbi òdodo.

Verse 56

وَقَالَ ٱلَّذِينَ أُوتُوا۟ ٱلْعِلْمَ وَٱلْإِيمَـٰنَ لَقَدْ لَبِثْتُمْ فِى كِتَـٰبِ ٱللَّهِ إِلَىٰ يَوْمِ ٱلْبَعْثِ ۖ فَهَـٰذَا يَوْمُ ٱلْبَعْثِ وَلَـٰكِنَّكُمْ كُنتُمْ لَا تَعْلَمُونَ

Transliteration waqāla alladhīna ūtū l-ʿil'ma wal-īmāna laqad labith'tum fī kitābi l-lahi ilā yawmi l-baʿthi fahādhā yawmu l-baʿthi walākinnakum kuntum lā taʿlamūna

Yoruba Àwọn tí A fún ní ìmọ̀ àti ìgbàgbọ́ òdodo yóò sọ pé: “Dájúdájú nínú àkọsílẹ̀ ti Allāhu, ẹ ti gbé ilé ayé títí Ọjọ́ Àjíǹde (fi tó). Nítorí náà, èyí ni Ọjọ́ Àjíǹde, ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò mọ̀.”

Verse 57

فَيَوْمَئِذٍ لَّا يَنفَعُ ٱلَّذِينَ ظَلَمُوا۟ مَعْذِرَتُهُمْ وَلَا هُمْ يُسْتَعْتَبُونَ

Transliteration fayawma-idhin lā yanfaʿu alladhīna ẓalamū maʿdhiratuhum walā hum yus'taʿtabūna

Yoruba Nítorí náà ní ọjọ́ yẹn, àwọn tó ṣàbòsí, àwáwí wọn kò níí ṣe wọ́n ní àǹfààní. Wọn kò sì níí fún wọn ní àyè láti ṣe ohun tí wọn yóò fi rí ìyọ́nú Allāhu.

Verse 58

وَلَقَدْ ضَرَبْنَا لِلنَّاسِ فِى هَـٰذَا ٱلْقُرْءَانِ مِن كُلِّ مَثَلٍ ۚ وَلَئِن جِئْتَهُم بِـَٔايَةٍ لَّيَقُولَنَّ ٱلَّذِينَ كَفَرُوٓا۟ إِنْ أَنتُمْ إِلَّا مُبْطِلُونَ

Transliteration walaqad ḍarabnā lilnnāsi fī hādhā l-qur'āni min kulli mathalin wala-in ji'tahum biāyatin layaqūlanna alladhīna kafarū in antum illā mub'ṭilūna

Yoruba A kúkú ti fi oríṣiríṣi àkàwé lélẹ̀ nínú al-Ƙur’ān yìí fún àwọn ènìyàn. Dájúdájú tí o bá mú āyah kan wá fún wọn, dájúdájú àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ yóò wí pé: “Ẹ̀yin (Òjíṣẹ́) kò jẹ́ kiní kan bí kò ṣe òpùrọ́.”

Verse 59

كَذَٰلِكَ يَطْبَعُ ٱللَّهُ عَلَىٰ قُلُوبِ ٱلَّذِينَ لَا يَعْلَمُونَ

Transliteration kadhālika yaṭbaʿu l-lahu ʿalā qulūbi alladhīna lā yaʿlamūna

Yoruba Báyẹn ni Allāhu ṣe ń fi èdídí dí ọkàn àwọn tí kò nímọ̀.

Verse 60

فَٱصْبِرْ إِنَّ وَعْدَ ٱللَّهِ حَقٌّ ۖ وَلَا يَسْتَخِفَّنَّكَ ٱلَّذِينَ لَا يُوقِنُونَ

Transliteration fa-iṣ'bir inna waʿda l-lahi ḥaqqun walā yastakhiffannaka alladhīna lā yūqinūna

Yoruba Nítorí náà, ṣe sùúrù. Dájúdájú àdéhùn Allāhu ni òdodo. Má ṣe jẹ́ kí àwọn tí kò mọ àmọ̀dájú (nípa Ọjọ́ ẹ̀san) sọ ọ́ di òpè (bí irú wọn).

Read Surah Ar-Rum in another language

All languages

All 114 surahs in Yoruba: the Qur’an in Yoruba.

Learn it in MyDugsi

Yoruba translation: Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni, from Quran.com. Transliteration: Quran.com. Recitation: Mishary Alafasy, from EveryAyah.com. MyDugsi is a learning aid, not a replacement for a qualified teacher.