MyDugsiStart learning

Surah Al-Jathiyah in Yoruba: translation and audio

Surah 45 · الجاثية · The Crouching · 37 verses

Surah Al-Jathiyah verse by verse: the Arabic with a recitation you can repeat, the transliteration, and the Yoruba translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni. For the meaning of every word, see Surah Al-Jathiyah word by word in English.

Verse 1

حمٓ

Transliteration hha-meem

Yoruba Hā mīm. (Allāhu ló mọ ohun tí Ó gbàlérò pẹ̀lú àwọn háràfí náà.)1

Verse 2

تَنزِيلُ ٱلْكِتَـٰبِ مِنَ ٱللَّهِ ٱلْعَزِيزِ ٱلْحَكِيمِ

Transliteration tanzīlu l-kitābi mina l-lahi l-ʿazīzi l-ḥakīmi

Yoruba Tírà náà sọ̀kalẹ̀ díẹ̀ díẹ̀láti ọ̀dọ̀ Allāhu, Alágbára, Ọlọ́gbọ́n.

Verse 3

إِنَّ فِى ٱلسَّمَـٰوَٰتِ وَٱلْأَرْضِ لَـَٔايَـٰتٍ لِّلْمُؤْمِنِينَ

Transliteration inna fī l-samāwāti wal-arḍi laāyātin lil'mu'minīna

Yoruba Dájúdájú nínú àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ àwọn àmì wà (nínú wọn) fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo.

Verse 4

وَفِى خَلْقِكُمْ وَمَا يَبُثُّ مِن دَآبَّةٍ ءَايَـٰتٌ لِّقَوْمٍ يُوقِنُونَ

Transliteration wafī khalqikum wamā yabuthu min dābbatin āyātun liqawmin yūqinūna

Yoruba Àwọn àmì wà nínú ìṣẹ̀dá yín àti ohun tí Allāhu ń fọ́nká (sórí ilẹ̀) nínú àwọn n̄ǹkan abẹ̀mí; (àmì wà nínú wọn) fún ìjọ tó ní àmọ̀dájú.1

Verse 5

وَٱخْتِلَـٰفِ ٱلَّيْلِ وَٱلنَّهَارِ وَمَآ أَنزَلَ ٱللَّهُ مِنَ ٱلسَّمَآءِ مِن رِّزْقٍ فَأَحْيَا بِهِ ٱلْأَرْضَ بَعْدَ مَوْتِهَا وَتَصْرِيفِ ٱلرِّيَـٰحِ ءَايَـٰتٌ لِّقَوْمٍ يَعْقِلُونَ

Transliteration wa-ikh'tilāfi al-layli wal-nahāri wamā anzala l-lahu mina l-samāi min riz'qin fa-aḥyā bihi l-arḍa baʿda mawtihā wataṣrīfi l-riyāḥi āyātun liqawmin yaʿqilūna

Yoruba (Nínú) ìtẹ̀léǹtẹ̀lé òru àti ọ̀sán, àti ohun tí Allāhu ń sọ̀kalẹ̀ ní arísìkí, tí Ó ń fi sọ ilẹ̀ di àyè lẹ́yìn tó ti kú àti ìyípadà atẹ́gùn, àwọn àmì tún wà (nínú wọn) fún ìjọ tó ní làákàyè.

Verse 6

تِلْكَ ءَايَـٰتُ ٱللَّهِ نَتْلُوهَا عَلَيْكَ بِٱلْحَقِّ ۖ فَبِأَىِّ حَدِيثٍۭ بَعْدَ ٱللَّهِ وَءَايَـٰتِهِۦ يُؤْمِنُونَ

Transliteration til'ka āyātu l-lahi natlūhā ʿalayka bil-ḥaqi fabi-ayyi ḥadīthin baʿda l-lahi waāyātihi yu'minūna

Yoruba Ìwọ̀nyí ni àwọn āyah Allāhu tí À ń ké (ní kéú) fún ọ pẹ̀lú òdodo. Nítorí náà, ọ̀rọ̀ wo lẹ́yìn (ọ̀rọ̀) Allāhu àti àwọn àmì Rẹ̀ ni wọn yóò tún gbàgbọ́?

Verse 7

وَيْلٌ لِّكُلِّ أَفَّاكٍ أَثِيمٍ

Transliteration waylun likulli affākin athīmin

Yoruba Ègbé ni fún gbogbo ògbólógbòó òpùrọ́, ògbólógbòó ẹlẹ́ṣẹ̀,

Verse 8

يَسْمَعُ ءَايَـٰتِ ٱللَّهِ تُتْلَىٰ عَلَيْهِ ثُمَّ يُصِرُّ مُسْتَكْبِرًا كَأَن لَّمْ يَسْمَعْهَا ۖ فَبَشِّرْهُ بِعَذَابٍ أَلِيمٍ

Transliteration yasmaʿu āyāti l-lahi tut'lā ʿalayhi thumma yuṣirru mus'takbiran ka-an lam yasmaʿhā fabashir'hu biʿadhābin alīmin

Yoruba tí ó ń gbọ́ àwọn āyah Allāhu, tí wọ́n ń ké e fún un, lẹ́yìn náà, tí ó takú (sórí irọ́) ní ti ìgbéraga bí ẹni pé kò gbọ́ ọ. Fún un ní ìró ìyà ẹlẹ́ta-eléro.

Verse 9

وَإِذَا عَلِمَ مِنْ ءَايَـٰتِنَا شَيْـًٔا ٱتَّخَذَهَا هُزُوًا ۚ أُو۟لَـٰٓئِكَ لَهُمْ عَذَابٌ مُّهِينٌ

Transliteration wa-idhā ʿalima min āyātinā shayan ittakhadhahā huzuwan ulāika lahum ʿadhābun muhīnun

Yoruba Nígbà tí ó bá nímọ̀ nípa kiní kan nínú àwọn āyah Wa (tí òun náà jẹ́rìí sí òdodo rẹ̀), ó máa mú un ní n̄ǹkan yẹ̀yẹ́. Àwọn wọ̀nyẹn ni ìyà tí í yẹpẹrẹ ẹ̀dá ń bẹ fún.

Verse 10

مِّن وَرَآئِهِمْ جَهَنَّمُ ۖ وَلَا يُغْنِى عَنْهُم مَّا كَسَبُوا۟ شَيْـًٔا وَلَا مَا ٱتَّخَذُوا۟ مِن دُونِ ٱللَّهِ أَوْلِيَآءَ ۖ وَلَهُمْ عَذَابٌ عَظِيمٌ

Transliteration min warāihim jahannamu walā yugh'nī ʿanhum mā kasabū shayan walā mā ittakhadhū min dūni l-lahi awliyāa walahum ʿadhābun ʿaẓīmun

Yoruba Iná Jahanamọ wà níwájú wọn. Ohun tí wọ́n ṣe níṣẹ́ àti ohun tí wọ́n mú ní alátìlẹ́yìn lẹ́yìn Allāhu kò sì níí rọ̀ wọ́n lọ́rọ̀ kan níbi ìyà. Ìyà ńlá sì wà fún wọn.

Verse 11

هَـٰذَا هُدًى ۖ وَٱلَّذِينَ كَفَرُوا۟ بِـَٔايَـٰتِ رَبِّهِمْ لَهُمْ عَذَابٌ مِّن رِّجْزٍ أَلِيمٌ

Transliteration hādhā hudan wa-alladhīna kafarū biāyāti rabbihim lahum ʿadhābun min rij'zin alīmun

Yoruba Èyí ni ìmọ̀nà. Àwọn tó sì ṣàì gbàgbọ́ nínú àwọn āyah Olúwa wọn, ìyà ẹlẹ́gbin ẹlẹ́ta-eléro wà fún wọn.

Verse 12

۞ ٱللَّهُ ٱلَّذِى سَخَّرَ لَكُمُ ٱلْبَحْرَ لِتَجْرِىَ ٱلْفُلْكُ فِيهِ بِأَمْرِهِۦ وَلِتَبْتَغُوا۟ مِن فَضْلِهِۦ وَلَعَلَّكُمْ تَشْكُرُونَ

Transliteration al-lahu alladhī sakhara lakumu l-baḥra litajriya l-ful'ku fīhi bi-amrihi walitabtaghū min faḍlihi walaʿallakum tashkurūna

Yoruba Allāhu ni Ẹni tí Ó rọ agbami odò fún yín nítorí kí àwọn ọkọ̀ ojú-omi lè rìn nínú rẹ̀ pẹ̀lú àṣẹ Rẹ̀ àti nítorí kí ẹ tún lè wá nínú oore Rẹ̀ àti nítorí kí ẹ lè dúpẹ́ (fún Un).

Verse 13

وَسَخَّرَ لَكُم مَّا فِى ٱلسَّمَـٰوَٰتِ وَمَا فِى ٱلْأَرْضِ جَمِيعًا مِّنْهُ ۚ إِنَّ فِى ذَٰلِكَ لَـَٔايَـٰتٍ لِّقَوْمٍ يَتَفَكَّرُونَ

Transliteration wasakhara lakum mā fī l-samāwāti wamā fī l-arḍi jamīʿan min'hu inna fī dhālika laāyātin liqawmin yatafakkarūna

Yoruba Ó tún rọ ohunkóhun tó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ohunkóhun tó wà nínú ilẹ̀ pátápátá fún yín láti ọ̀dọ̀ Rẹ̀. Dájúdájú àwọn àmì wà nínú ìyẹn fún ìjọ tó ní àròjinlẹ̀.

Verse 14

قُل لِّلَّذِينَ ءَامَنُوا۟ يَغْفِرُوا۟ لِلَّذِينَ لَا يَرْجُونَ أَيَّامَ ٱللَّهِ لِيَجْزِىَ قَوْمًۢا بِمَا كَانُوا۟ يَكْسِبُونَ

Transliteration qul lilladhīna āmanū yaghfirū lilladhīna lā yarjūna ayyāma l-lahi liyajziya qawman bimā kānū yaksibūna

Yoruba Sọ fún àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo pé kí wọ́n ṣàmójú kúrò fún àwọn tí kò retí àwọn ọjọ́ (tí) Allāhu (yóò ṣe àrànṣe fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo) nítorí kí Ó lè san ẹ̀san fún ìjọ kan nípa ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́.

Verse 15

مَنْ عَمِلَ صَـٰلِحًا فَلِنَفْسِهِۦ ۖ وَمَنْ أَسَآءَ فَعَلَيْهَا ۖ ثُمَّ إِلَىٰ رَبِّكُمْ تُرْجَعُونَ

Transliteration man ʿamila ṣāliḥan falinafsihi waman asāa faʿalayhā thumma ilā rabbikum tur'jaʿūna

Yoruba Ẹníkẹ́ni tí ó bá ṣe iṣẹ́ rere, fún ẹ̀mí ara rẹ̀ ni. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì ṣe iṣẹ́ aburú, fún ẹ̀mí ara rẹ̀ ni. Lẹ́yìn náà, ọ̀dọ̀ Olúwa yín ni wọn yóò da yín padà sí.

Verse 16

وَلَقَدْ ءَاتَيْنَا بَنِىٓ إِسْرَٰٓءِيلَ ٱلْكِتَـٰبَ وَٱلْحُكْمَ وَٱلنُّبُوَّةَ وَرَزَقْنَـٰهُم مِّنَ ٱلطَّيِّبَـٰتِ وَفَضَّلْنَـٰهُمْ عَلَى ٱلْعَـٰلَمِينَ

Transliteration walaqad ātaynā banī is'rāīla l-kitāba wal-ḥuk'ma wal-nubuwata warazaqnāhum mina l-ṭayibāti wafaḍḍalnāhum ʿalā l-ʿālamīna

Yoruba Dájúdájú A fún àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl ní Tírà àti ìdájọ́ ṣíṣe àti ipò Ànábì. A sì ṣe arísìkí fún wọn nínú àwọn n̄ǹkan dáadáa. A sì ṣoore àjùlọ fún wọn lórí àwọn ẹ̀dá (àsìkò tiwọn).

Verse 17

وَءَاتَيْنَـٰهُم بَيِّنَـٰتٍ مِّنَ ٱلْأَمْرِ ۖ فَمَا ٱخْتَلَفُوٓا۟ إِلَّا مِنۢ بَعْدِ مَا جَآءَهُمُ ٱلْعِلْمُ بَغْيًۢا بَيْنَهُمْ ۚ إِنَّ رَبَّكَ يَقْضِى بَيْنَهُمْ يَوْمَ ٱلْقِيَـٰمَةِ فِيمَا كَانُوا۟ فِيهِ يَخْتَلِفُونَ

Transliteration waātaynāhum bayyinātin mina l-amri famā ikh'talafū illā min baʿdi mā jāahumu l-ʿil'mu baghyan baynahum inna rabbaka yaqḍī baynahum yawma l-qiyāmati fīmā kānū fīhi yakhtalifūna

Yoruba A tún fún wọn ní àwọn ẹ̀rí tó yanjú nípa ọ̀rọ̀ náà. Nítorí náà, wọn kò pín sí ìjọ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ àfi lẹ́yìn tí ìmọ̀ (’Islām) dé bá wọn ní ti ìlara láààrin ara wọn (sí àwọn Ànábì). Dájúdájú Olúwa rẹ l’Ó máa ṣe ìdájọ́ láààrin wọn ní Ọjọ́ Àjíǹde nípa n̄ǹkan tí wọ́n ń yapa-ẹnu lórí rẹ̀.

Verse 18

ثُمَّ جَعَلْنَـٰكَ عَلَىٰ شَرِيعَةٍ مِّنَ ٱلْأَمْرِ فَٱتَّبِعْهَا وَلَا تَتَّبِعْ أَهْوَآءَ ٱلَّذِينَ لَا يَعْلَمُونَ

Transliteration thumma jaʿalnāka ʿalā sharīʿatin mina l-amri fa-ittabiʿ'hā walā tattabiʿ ahwāa alladhīna lā yaʿlamūna

Yoruba Lẹ́yìn náà, A fi ọ́ sí ojú ọ̀nà kan nínú ọ̀rọ̀ náà (ẹ̀sìn ’Islām). Nítorí náà, tẹ̀lé e. Kí o sì má ṣe tẹ̀lé ìfẹ́-inú àwọn tí kò nímọ̀.

Verse 19

إِنَّهُمْ لَن يُغْنُوا۟ عَنكَ مِنَ ٱللَّهِ شَيْـًٔا ۚ وَإِنَّ ٱلظَّـٰلِمِينَ بَعْضُهُمْ أَوْلِيَآءُ بَعْضٍ ۖ وَٱللَّهُ وَلِىُّ ٱلْمُتَّقِينَ

Transliteration innahum lan yugh'nū ʿanka mina l-lahi shayan wa-inna l-ẓālimīna baʿḍuhum awliyāu baʿḍin wal-lahu waliyyu l-mutaqīna

Yoruba Dájúdájú wọn kò lè rọ̀ ọ́ lọ́rọ̀ kiní kan níbi ìyà ní ọ̀dọ̀ Allāhu. Àti pé dájúdájú àwọn alábòsí, apá kan wọn lọ̀rẹ́ apá kan. Allāhu sì ni Ọ̀rẹ́ àwọn olùbẹ̀rù (Rẹ̀).

Verse 20

هَـٰذَا بَصَـٰٓئِرُ لِلنَّاسِ وَهُدًى وَرَحْمَةٌ لِّقَوْمٍ يُوقِنُونَ

Transliteration hādhā baṣāiru lilnnāsi wahudan waraḥmatun liqawmin yūqinūna

Yoruba Èyí ni ìmọ̀ àmọ̀dájú àti ẹ̀rí fún àwọn ènìyàn. Ìmọ̀nà àti ìkẹ́ ni fún ìjọ tó ní àmọ̀dájú.

Verse 21

أَمْ حَسِبَ ٱلَّذِينَ ٱجْتَرَحُوا۟ ٱلسَّيِّـَٔاتِ أَن نَّجْعَلَهُمْ كَٱلَّذِينَ ءَامَنُوا۟ وَعَمِلُوا۟ ٱلصَّـٰلِحَـٰتِ سَوَآءً مَّحْيَاهُمْ وَمَمَاتُهُمْ ۚ سَآءَ مَا يَحْكُمُونَ

Transliteration am ḥasiba alladhīna ij'taraḥū l-sayiāti an najʿalahum ka-alladhīna āmanū waʿamilū l-ṣāliḥāti sawāan maḥyāhum wamamātuhum sāa mā yaḥkumūna

Yoruba Tàbí àwọn tó ń ṣe iṣẹ́ aburú lérò pé A máa ṣe wọ́n gẹ́gẹ́ bí (A ti ṣe) àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe àwọn iṣẹ́ rere, kí ìṣẹ́mí ayé wọn àti ikú wọn rí bákan náà? Ohun tí wọ́n ń dá ní ẹjọ́, ó burú.

Verse 22

وَخَلَقَ ٱللَّهُ ٱلسَّمَـٰوَٰتِ وَٱلْأَرْضَ بِٱلْحَقِّ وَلِتُجْزَىٰ كُلُّ نَفْسٍۭ بِمَا كَسَبَتْ وَهُمْ لَا يُظْلَمُونَ

Transliteration wakhalaqa l-lahu l-samāwāti wal-arḍa bil-ḥaqi walituj'zā kullu nafsin bimā kasabat wahum lā yuẓ'lamūna

Yoruba Allāhu ṣẹ̀dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ pẹ̀lú òdodo àti nítorí kí Á lè san ẹ̀mí kọ̀ọ̀kan ní ẹ̀san n̄ǹkan tí ó ṣe níṣẹ́. A kò sì níí ṣe àbòsí sí wọn.

Verse 23

أَفَرَءَيْتَ مَنِ ٱتَّخَذَ إِلَـٰهَهُۥ هَوَىٰهُ وَأَضَلَّهُ ٱللَّهُ عَلَىٰ عِلْمٍ وَخَتَمَ عَلَىٰ سَمْعِهِۦ وَقَلْبِهِۦ وَجَعَلَ عَلَىٰ بَصَرِهِۦ غِشَـٰوَةً فَمَن يَهْدِيهِ مِنۢ بَعْدِ ٱللَّهِ ۚ أَفَلَا تَذَكَّرُونَ

Transliteration afara-ayta mani ittakhadha ilāhahu hawāhu wa-aḍallahu l-lahu ʿalā ʿil'min wakhatama ʿalā samʿihi waqalbihi wajaʿala ʿalā baṣarihi ghishāwatan faman yahdīhi min baʿdi l-lahi afalā tadhakkarūna

Yoruba Sọ fún mi nípa ẹni tí ó sọ ìfẹ́-inú rẹ̀ di ọlọ́hun rẹ̀, tí Allāhu sì ṣì í lọ́nà pẹ̀lú ìmọ̀ tí Ó sì fi èdídí dí ìgbọ́rọ̀ rẹ̀ àti ọkàn rẹ̀, tí Ó tún fi èbìbò bo ojú rẹ̀! Ta ni ó máa fi ọ̀nà mọ̀ ọ́n lẹ́yìn Allāhu? Ṣé ẹ kò níí lo ìrántí ni?

Verse 24

وَقَالُوا۟ مَا هِىَ إِلَّا حَيَاتُنَا ٱلدُّنْيَا نَمُوتُ وَنَحْيَا وَمَا يُهْلِكُنَآ إِلَّا ٱلدَّهْرُ ۚ وَمَا لَهُم بِذَٰلِكَ مِنْ عِلْمٍ ۖ إِنْ هُمْ إِلَّا يَظُنُّونَ

Transliteration waqālū mā hiya illā ḥayātunā l-dun'yā namūtu wanaḥyā wamā yuh'likunā illā l-dahru wamā lahum bidhālika min ʿil'min in hum illā yaẓunnūna

Yoruba Wọ́n wí pé: “Kò sí ìṣẹ̀mí kan mọ́ bí kò ṣe ìṣẹ̀mí ayé wa yìí; à ń kú, a sì ń ṣẹ̀mí. Àti pé kò sí n̄ǹkan tó ń pa wá bí kò ṣe ìgbà.” Wọn kò sì ní ìmọ̀ kan nípa ìyẹn; wọn kò ṣe kiní kan bí kò ṣe pé wọ́n ń ro èròkérò.

Verse 25

وَإِذَا تُتْلَىٰ عَلَيْهِمْ ءَايَـٰتُنَا بَيِّنَـٰتٍ مَّا كَانَ حُجَّتَهُمْ إِلَّآ أَن قَالُوا۟ ٱئْتُوا۟ بِـَٔابَآئِنَآ إِن كُنتُمْ صَـٰدِقِينَ

Transliteration wa-idhā tut'lā ʿalayhim āyātunā bayyinātin mā kāna ḥujjatahum illā an qālū i'tū biābāinā in kuntum ṣādiqīna

Yoruba Àti pé nígbà tí wọ́n bá ń ké àwọn āyah Wa tó yanjú fún wọn, àwíjàre wọn kò jẹ́ kiní kan àyàfi kí wọ́n wí pé: “Ẹ mú àwọn bàbá wa wá tí ẹ bá jẹ́ olódodo.”

Verse 26

قُلِ ٱللَّهُ يُحْيِيكُمْ ثُمَّ يُمِيتُكُمْ ثُمَّ يَجْمَعُكُمْ إِلَىٰ يَوْمِ ٱلْقِيَـٰمَةِ لَا رَيْبَ فِيهِ وَلَـٰكِنَّ أَكْثَرَ ٱلنَّاسِ لَا يَعْلَمُونَ

Transliteration quli l-lahu yuḥ'yīkum thumma yumītukum thumma yajmaʿukum ilā yawmi l-qiyāmati lā rayba fīhi walākinna akthara l-nāsi lā yaʿlamūna

Yoruba Sọ pé: “Allāhu l’Ó ń sọ yín di alààyè. Lẹ́yìn náà, Ó máa sọ yín di òkú. Lẹ́yìn náà, Ó máa ko yín jọ fún Ọjọ́ Àjíǹde, kò sí iyèméjì nínú rẹ̀, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ènìyàn ni kò mọ̀.

Verse 27

وَلِلَّهِ مُلْكُ ٱلسَّمَـٰوَٰتِ وَٱلْأَرْضِ ۚ وَيَوْمَ تَقُومُ ٱلسَّاعَةُ يَوْمَئِذٍ يَخْسَرُ ٱلْمُبْطِلُونَ

Transliteration walillahi mul'ku l-samāwāti wal-arḍi wayawma taqūmu l-sāʿatu yawma-idhin yakhsaru l-mub'ṭilūna

Yoruba Àti pé ti Allāhu ni ìjọba àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. (Rántí) ọjọ́ tí Àkókò náà máa ṣẹlẹ̀; ọjọ́ yẹn ni àwọn òpùrọ́ máa ṣòfò.

Verse 28

وَتَرَىٰ كُلَّ أُمَّةٍ جَاثِيَةً ۚ كُلُّ أُمَّةٍ تُدْعَىٰٓ إِلَىٰ كِتَـٰبِهَا ٱلْيَوْمَ تُجْزَوْنَ مَا كُنتُمْ تَعْمَلُونَ

Transliteration watarā kulla ummatin jāthiyatan kullu ummatin tud'ʿā ilā kitābihā l-yawma tuj'zawna mā kuntum taʿmalūna

Yoruba O sì máa rí gbogbo ìjọ kọ̀ọ̀kan lórí ìkúnlẹ̀. Wọn yó sì máa pe gbogbo ìjọ kọ̀ọ̀kan síbi ìwé iṣẹ́ wọn. Ní òní ni A óò san yín ní ẹ̀san ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.

Verse 29

هَـٰذَا كِتَـٰبُنَا يَنطِقُ عَلَيْكُم بِٱلْحَقِّ ۚ إِنَّا كُنَّا نَسْتَنسِخُ مَا كُنتُمْ تَعْمَلُونَ

Transliteration hādhā kitābunā yanṭiqu ʿalaykum bil-ḥaqi innā kunnā nastansikhu mā kuntum taʿmalūna

Yoruba Èyí ni ìwé àkọ́sílẹ̀ Wa, tí ó ń sọ òdodo nípa yín. Dájúdájú Àwa ń ṣe àkọsílẹ̀ ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.

Verse 30

فَأَمَّا ٱلَّذِينَ ءَامَنُوا۟ وَعَمِلُوا۟ ٱلصَّـٰلِحَـٰتِ فَيُدْخِلُهُمْ رَبُّهُمْ فِى رَحْمَتِهِۦ ۚ ذَٰلِكَ هُوَ ٱلْفَوْزُ ٱلْمُبِينُ

Transliteration fa-ammā alladhīna āmanū waʿamilū l-ṣāliḥāti fayud'khiluhum rabbuhum fī raḥmatihi dhālika huwa l-fawzu l-mubīnu

Yoruba Ní ti àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe àwọn iṣẹ́ rere, Olúwa wọn yóò fi wọ́n sínú ìkẹ́ Rẹ̀. Ìyẹn ni èrèǹjẹ pọ́nńbélé.

Verse 31

وَأَمَّا ٱلَّذِينَ كَفَرُوٓا۟ أَفَلَمْ تَكُنْ ءَايَـٰتِى تُتْلَىٰ عَلَيْكُمْ فَٱسْتَكْبَرْتُمْ وَكُنتُمْ قَوْمًا مُّجْرِمِينَ

Transliteration wa-ammā alladhīna kafarū afalam takun āyātī tut'lā ʿalaykum fa-is'takbartum wakuntum qawman muj'rimīna

Yoruba Ní ti àwọn tó sì ṣàì gbàgbọ́, (A óò bi wọ́n léèrè pé:) “Ǹjẹ́ wọn kì í ké àwọn āyah Mi fún yín bí?” Ṣùgbọ́n ẹ ṣègbéraga. Ẹ sì jẹ́ ìjọ ẹlẹ́ṣẹ̀.

Verse 32

وَإِذَا قِيلَ إِنَّ وَعْدَ ٱللَّهِ حَقٌّ وَٱلسَّاعَةُ لَا رَيْبَ فِيهَا قُلْتُم مَّا نَدْرِى مَا ٱلسَّاعَةُ إِن نَّظُنُّ إِلَّا ظَنًّا وَمَا نَحْنُ بِمُسْتَيْقِنِينَ

Transliteration wa-idhā qīla inna waʿda l-lahi ḥaqqun wal-sāʿatu lā rayba fīhā qul'tum mā nadrī mā l-sāʿatu in naẓunnu illā ẓannan wamā naḥnu bimus'tayqinīna

Yoruba Nígbà tí a bá sọ pé: “Dájúdájú àdéhùn Allāhu ni òdodo. Àti pé Àkókò náà, kò sí iyèméjì nínú rẹ̀.” Ẹ̀yin ń wí pé: “Àwa kò mọ ohun tí Àkókò náà jẹ́. Àwa kò sì rò ó sí kiní kan bí kò ṣe èròkérò; àwa kò sì ní àmọ̀dájú (nípa rẹ̀).”

Verse 33

وَبَدَا لَهُمْ سَيِّـَٔاتُ مَا عَمِلُوا۟ وَحَاقَ بِهِم مَّا كَانُوا۟ بِهِۦ يَسْتَهْزِءُونَ

Transliteration wabadā lahum sayyiātu mā ʿamilū waḥāqa bihim mā kānū bihi yastahziūna

Yoruba Àwọn aburú ohun tí wọ́n ṣe níṣẹ́ sì hàn sí wọn. Àti pé ohun tí wọ́n ń fi ṣe yẹ̀yẹ́ sì dìyà tó yí wọn po.

Verse 34

وَقِيلَ ٱلْيَوْمَ نَنسَىٰكُمْ كَمَا نَسِيتُمْ لِقَآءَ يَوْمِكُمْ هَـٰذَا وَمَأْوَىٰكُمُ ٱلنَّارُ وَمَا لَكُم مِّن نَّـٰصِرِينَ

Transliteration waqīla l-yawma nansākum kamā nasītum liqāa yawmikum hādhā wamawākumu l-nāru wamā lakum min nāṣirīna

Yoruba Wọ́n sì máa sọ (fún wọn) pé: “Ní òní, Àwa yóò gbàgbé yín (sínú Iná) gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin náà ṣe gbàgbé ìpàdé ọjọ́ yín (òní) yìí. Iná sì ni ibùgbé yín. Àti pé kò níí sí àwọn olùrànlọ́wọ́ fún yín.”

Verse 35

ذَٰلِكُم بِأَنَّكُمُ ٱتَّخَذْتُمْ ءَايَـٰتِ ٱللَّهِ هُزُوًا وَغَرَّتْكُمُ ٱلْحَيَوٰةُ ٱلدُّنْيَا ۚ فَٱلْيَوْمَ لَا يُخْرَجُونَ مِنْهَا وَلَا هُمْ يُسْتَعْتَبُونَ

Transliteration dhālikum bi-annakumu ittakhadhtum āyāti l-lahi huzuwan wagharratkumu l-ḥayatu l-dun'yā fal-yawma lā yukh'rajūna min'hā walā hum yus'taʿtabūna

Yoruba Báyẹn ni nítorí pé, ẹ sọ àwọn āyah Allāhu di n̄ǹkan yẹ̀yẹ́. Àti pé ìṣẹ̀mí ayé tàn yín jẹ. Nítorí náà, ní òní wọn kò níí mú wọn jáde kúrò nínú Iná. Wọn kò sì níí fún wọn ní àyè láti ṣe ohun tí wọn yóò fi rí ìyọ́nú Allāhu.

Verse 36

فَلِلَّهِ ٱلْحَمْدُ رَبِّ ٱلسَّمَـٰوَٰتِ وَرَبِّ ٱلْأَرْضِ رَبِّ ٱلْعَـٰلَمِينَ

Transliteration falillahi l-ḥamdu rabbi l-samāwāti warabbi l-arḍi rabbi l-ʿālamīna

Yoruba Nítorí náà, gbogbo ẹyìn ń jẹ́ ti Allāhu, Olúwa àwọn sánmọ̀ àti Olúwa ilẹ̀, Olúwa gbogbo ẹ̀dá.

Verse 37

وَلَهُ ٱلْكِبْرِيَآءُ فِى ٱلسَّمَـٰوَٰتِ وَٱلْأَرْضِ ۖ وَهُوَ ٱلْعَزِيزُ ٱلْحَكِيمُ

Transliteration walahu l-kib'riyāu fī l-samāwāti wal-arḍi wahuwa l-ʿazīzu l-ḥakīmu

Yoruba TiRẹ̀ ni títóbi nínú àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Òun sì ni Alágbára, Ọlọ́gbọ́n.

Read Surah Al-Jathiyah in another language

All languages

All 114 surahs in Yoruba: the Qur’an in Yoruba.

Learn it in MyDugsi

Yoruba translation: Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni, from Quran.com. Transliteration: Quran.com. Recitation: Mishary Alafasy, from EveryAyah.com. MyDugsi is a learning aid, not a replacement for a qualified teacher.