MyDugsiStart learning

Surah Al-Furqan in Yoruba: translation and audio

Surah 25 · الفرقان · The Criterion · 77 verses

Surah Al-Furqan verse by verse: the Arabic with a recitation you can repeat, the transliteration, and the Yoruba translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni. For the meaning of every word, see Surah Al-Furqan word by word in English.

Verse 1

تَبَارَكَ ٱلَّذِى نَزَّلَ ٱلْفُرْقَانَ عَلَىٰ عَبْدِهِۦ لِيَكُونَ لِلْعَـٰلَمِينَ نَذِيرًا

Transliteration tabāraka alladhī nazzala l-fur'qāna ʿalā ʿabdihi liyakūna lil'ʿālamīna nadhīran

Yoruba Ìbùkún ni fún Ẹni tí Ó sọ ọ̀rọ̀-ìpínyà (ohun tó ń ṣòpínyà láààrin òdodo àti irọ́) kalẹ̀ fún ẹrúsìn Rẹ̀ nítorí kí ó lè jẹ́ olùkìlọ̀ fún gbogbo ẹ̀dá.

Verse 2

ٱلَّذِى لَهُۥ مُلْكُ ٱلسَّمَـٰوَٰتِ وَٱلْأَرْضِ وَلَمْ يَتَّخِذْ وَلَدًا وَلَمْ يَكُن لَّهُۥ شَرِيكٌ فِى ٱلْمُلْكِ وَخَلَقَ كُلَّ شَىْءٍ فَقَدَّرَهُۥ تَقْدِيرًا

Transliteration alladhī lahu mul'ku l-samāwāti wal-arḍi walam yattakhidh waladan walam yakun lahu sharīkun fī l-mul'ki wakhalaqa kulla shayin faqaddarahu taqdīran

Yoruba (Òun ni) Ẹni tí Ó ni ìjọba àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Kò mú ẹnì kan kan ní ọmọ. Kò sí akẹgbẹ́ fún Un nínú ìjọba (Rẹ̀). Ó dá gbogbo n̄ǹkan. Ó sì yan òdíwọ̀n (ìrísí, ìṣẹ̀mí àti àyànmọ́) fún un níwọ̀n-níwọ̀n.

Verse 3

وَٱتَّخَذُوا۟ مِن دُونِهِۦٓ ءَالِهَةً لَّا يَخْلُقُونَ شَيْـًٔا وَهُمْ يُخْلَقُونَ وَلَا يَمْلِكُونَ لِأَنفُسِهِمْ ضَرًّا وَلَا نَفْعًا وَلَا يَمْلِكُونَ مَوْتًا وَلَا حَيَوٰةً وَلَا نُشُورًا

Transliteration wa-ittakhadhū min dūnihi ālihatan lā yakhluqūna shayan wahum yukh'laqūna walā yamlikūna li-anfusihim ḍarran walā nafʿan walā yamlikūna mawtan walā ḥayatan walā nushūran

Yoruba (Àwọn aláìgbàgbọ́) sọ àwọn kan di ọlọ́hun lẹ́yìn Allāhu, àwọn tí kò lè dá n̄ǹkan kan, A sì dá wọn ni. Wọn kò sì ní ìkápá ìnira tàbí àǹfààní kan fún ẹ̀mí ara wọn. Àti pé wọn kò ní ìkápá lórí ikú, ìṣẹ̀mí àti àjíǹde.

Verse 4

وَقَالَ ٱلَّذِينَ كَفَرُوٓا۟ إِنْ هَـٰذَآ إِلَّآ إِفْكٌ ٱفْتَرَىٰهُ وَأَعَانَهُۥ عَلَيْهِ قَوْمٌ ءَاخَرُونَ ۖ فَقَدْ جَآءُو ظُلْمًا وَزُورًا

Transliteration waqāla alladhīna kafarū in hādhā illā if'kun if'tarāhu wa-aʿānahu ʿalayhi qawmun ākharūna faqad jāū ẓul'man wazūran

Yoruba Àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ wí pé: “Kí ni èyí bí kò ṣe àdápa irọ́ kan tí ó dá àdápa rẹ̀ (mọ́ Allāhu), tí àwọn ènìyàn mìíràn sì ràn án lọ́wọ́ lórí rẹ̀.” Dájúdájú (àwọn aláìgbàgbọ́) ti gbé àbòsí àti irọ́ dé.

Verse 5

وَقَالُوٓا۟ أَسَـٰطِيرُ ٱلْأَوَّلِينَ ٱكْتَتَبَهَا فَهِىَ تُمْلَىٰ عَلَيْهِ بُكْرَةً وَأَصِيلًا

Transliteration waqālū asāṭīru l-awalīna ik'tatabahā fahiya tum'lā ʿalayhi buk'ratan wa-aṣīlan

Yoruba Wọ́n tún wí pé: “Àkọsílẹ̀ àlọ́ àwọn ẹni àkọ́kọ́, tí ó ṣàdàkọ rẹ̀ ni. Òhun ni wọ́n ń pè fún un ní òwúrọ̀ àti ní ìrọ̀lẹ́.”

Verse 6

قُلْ أَنزَلَهُ ٱلَّذِى يَعْلَمُ ٱلسِّرَّ فِى ٱلسَّمَـٰوَٰتِ وَٱلْأَرْضِ ۚ إِنَّهُۥ كَانَ غَفُورًا رَّحِيمًا

Transliteration qul anzalahu alladhī yaʿlamu l-sira fī l-samāwāti wal-arḍi innahu kāna ghafūran raḥīman

Yoruba Sọ pé: “Ẹni tí Ó mọ ìkọ̀kọ̀ tí ń bẹ nínú àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ l’Ó sọ̀ ọ́ kalẹ̀. Dájúdájú Òun ni Ó ń jẹ́ Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.”

Verse 7

وَقَالُوا۟ مَالِ هَـٰذَا ٱلرَّسُولِ يَأْكُلُ ٱلطَّعَامَ وَيَمْشِى فِى ٱلْأَسْوَاقِ ۙ لَوْلَآ أُنزِلَ إِلَيْهِ مَلَكٌ فَيَكُونَ مَعَهُۥ نَذِيرًا

Transliteration waqālū māli hādhā l-rasūli yakulu l-ṭaʿāma wayamshī fī l-aswāqi lawlā unzila ilayhi malakun fayakūna maʿahu nadhīran

Yoruba Wọ́n tún wí pé: “Kí ló mú Òjíṣẹ́ yìí, tó ń jẹun, tó ń rìn nínú àwọn ọjà? Nítorí kí ni Wọn kò ṣe sọ mọlāika kan kalẹ̀ fún un kí ó lè jẹ́ olùkìlọ̀ pẹ̀lú rẹ̀?

Verse 8

أَوْ يُلْقَىٰٓ إِلَيْهِ كَنزٌ أَوْ تَكُونُ لَهُۥ جَنَّةٌ يَأْكُلُ مِنْهَا ۚ وَقَالَ ٱلظَّـٰلِمُونَ إِن تَتَّبِعُونَ إِلَّا رَجُلًا مَّسْحُورًا

Transliteration aw yul'qā ilayhi kanzun aw takūnu lahu jannatun yakulu min'hā waqāla l-ẓālimūna in tattabiʿūna illā rajulan masḥūran

Yoruba Tàbí (nítorí kí ni) wọn kò ṣe ju àpótí-ọrọ̀ kan sọ́dọ̀ rẹ̀, tàbí kí ó ní ọgbà oko kan tí ó ma máa jẹ nínú rẹ̀?” Àwọn alábòsí sì tún wí pé: “Ta ni ẹ̀ ń tẹ̀lé bí kò ṣe ọkùnrin eléèdì kan.”

Verse 9

ٱنظُرْ كَيْفَ ضَرَبُوا۟ لَكَ ٱلْأَمْثَـٰلَ فَضَلُّوا۟ فَلَا يَسْتَطِيعُونَ سَبِيلًا

Transliteration unẓur kayfa ḍarabū laka l-amthāla faḍallū falā yastaṭīʿūna sabīlan

Yoruba Wo bí wọ́n ṣe fún ọ ní àwọn àfiwé (burúkú)! Nítorí náà, wọ́n ti ṣìnà; wọn kò sì lè mọ̀nà.

Verse 10

تَبَارَكَ ٱلَّذِىٓ إِن شَآءَ جَعَلَ لَكَ خَيْرًا مِّن ذَٰلِكَ جَنَّـٰتٍ تَجْرِى مِن تَحْتِهَا ٱلْأَنْهَـٰرُ وَيَجْعَل لَّكَ قُصُورًۢا

Transliteration tabāraka alladhī in shāa jaʿala laka khayran min dhālika jannātin tajrī min taḥtihā l-anhāru wayajʿal laka quṣūran

Yoruba Ìbùkún ni fún Ẹni tí (ó jẹ́ pé) bí Ó bá fẹ́, Ó máa ṣoore tó dára ju ìyẹn fún ọ. (Ó sì máa jẹ́) àwọn ọgbà tí àwọn odò yóò máa ṣàn ní ìsàlẹ̀ rẹ̀. Ó sì máa fún ọ ni àwọn ààfin kan.

Verse 11

بَلْ كَذَّبُوا۟ بِٱلسَّاعَةِ ۖ وَأَعْتَدْنَا لِمَن كَذَّبَ بِٱلسَّاعَةِ سَعِيرًا

Transliteration bal kadhabū bil-sāʿati wa-aʿtadnā liman kadhaba bil-sāʿati saʿīran

Yoruba Ńṣe ni wọ́n pe Àkókò náà nírọ́. A sì ti pèsè Iná tó ń jo sílẹ̀ de ẹnikẹ́ni tí ó bá pe Àkókò náà nírọ́.

Verse 12

إِذَا رَأَتْهُم مِّن مَّكَانٍۭ بَعِيدٍ سَمِعُوا۟ لَهَا تَغَيُّظًا وَزَفِيرًا

Transliteration idhā ra-athum min makānin baʿīdin samiʿū lahā taghayyuẓan wazafīran

Yoruba Nígbà tí (Iná náà) bá rí wọn láti àyè kan tí ó jìnnà, wọn yó sì máa gbọ́ ohùn ìbínú àti kíkùn (rẹ̀).

Verse 13

وَإِذَآ أُلْقُوا۟ مِنْهَا مَكَانًا ضَيِّقًا مُّقَرَّنِينَ دَعَوْا۟ هُنَالِكَ ثُبُورًا

Transliteration wa-idhā ul'qū min'hā makānan ḍayyiqan muqarranīna daʿaw hunālika thubūran

Yoruba Nígbà tí wọ́n bá sì jù wọ́n sí àyè tó há gádígádí nínú (Iná), tí wọ́n de ọwọ́ wọn mọ́ wọn lọ́rùn, wọn yó sì máa kígbe ìparun níbẹ̀.

Verse 14

لَّا تَدْعُوا۟ ٱلْيَوْمَ ثُبُورًا وَٰحِدًا وَٱدْعُوا۟ ثُبُورًا كَثِيرًا

Transliteration lā tadʿū l-yawma thubūran wāḥidan wa-id'ʿū thubūran kathīran

Yoruba (A ó sọ pé): “Ẹ má ṣe kígbe ìparun ẹyọ kan, ẹ kígbe ìparun lọ́pọ̀lọ́pọ̀.”

Verse 15

قُلْ أَذَٰلِكَ خَيْرٌ أَمْ جَنَّةُ ٱلْخُلْدِ ٱلَّتِى وُعِدَ ٱلْمُتَّقُونَ ۚ كَانَتْ لَهُمْ جَزَآءً وَمَصِيرًا

Transliteration qul adhālika khayrun am jannatu l-khul'di allatī wuʿida l-mutaqūna kānat lahum jazāan wamaṣīran

Yoruba Sọ pé: “Ǹjẹ́ ìyẹn ló lóore jùlọ ni tàbí Ọgbà Ìdẹ̀ra gbére, èyí tí A ṣe ní àdéhùn fún àwọn olùbẹ̀rù Allāhu. Ó sì jẹ́ ẹ̀san àti ìkángun rere fún wọn.

Verse 16

لَّهُمْ فِيهَا مَا يَشَآءُونَ خَـٰلِدِينَ ۚ كَانَ عَلَىٰ رَبِّكَ وَعْدًا مَّسْـُٔولًا

Transliteration lahum fīhā mā yashāūna khālidīna kāna ʿalā rabbika waʿdan masūlan

Yoruba Ohunkóhun tí wọ́n bá ń fẹ́ wà fún wọn nínú rẹ̀. Olùṣegbére ni wọ́n (nínú rẹ̀). (Èyí) jẹ́ àdéhùn tí wọ́n ti tọ̀rọ̀ lọ́dọ̀ Olúwa rẹ.

Verse 17

وَيَوْمَ يَحْشُرُهُمْ وَمَا يَعْبُدُونَ مِن دُونِ ٱللَّهِ فَيَقُولُ ءَأَنتُمْ أَضْلَلْتُمْ عِبَادِى هَـٰٓؤُلَآءِ أَمْ هُمْ ضَلُّوا۟ ٱلسَّبِيلَ

Transliteration wayawma yaḥshuruhum wamā yaʿbudūna min dūni l-lahi fayaqūlu a-antum aḍlaltum ʿibādī hāulāi am hum ḍallū l-sabīla

Yoruba Àti pé (rántí) ọjọ́ tí (Allāhu) yóò kó àwọn abọ̀rìṣà àti n̄ǹkan tí wọ́n ń jọ́sìn fún lẹ́yìn Allāhu jọ, (Allāhu) yó sì sọ pé: “Ṣé ẹ̀yin l’ẹ ṣi àwọn ẹrúsìn Mi wọ̀nyí lọ́nà ni tàbí àwọn ni wọ́n ṣìnà (fúnra wọn)?”1

Verse 18

قَالُوا۟ سُبْحَـٰنَكَ مَا كَانَ يَنۢبَغِى لَنَآ أَن نَّتَّخِذَ مِن دُونِكَ مِنْ أَوْلِيَآءَ وَلَـٰكِن مَّتَّعْتَهُمْ وَءَابَآءَهُمْ حَتَّىٰ نَسُوا۟ ٱلذِّكْرَ وَكَانُوا۟ قَوْمًۢا بُورًا

Transliteration qālū sub'ḥānaka mā kāna yanbaghī lanā an nattakhidha min dūnika min awliyāa walākin mattaʿtahum waābāahum ḥattā nasū l-dhik'ra wakānū qawman būran

Yoruba Wọ́n wí pé: “Mímọ́ ni fún Ọ! Kò tọ́ fún wa láti mú àwọn kan ní alátìlẹ́yìn lẹ́yìn Rẹ. Ṣùgbọ́n Ìwọ l’O fún àwọn àti àwọn bàbá wọn ní ìgbádùn, títí wọ́n fi gbàgbé Ìrántí. Wọ́n sì jẹ́ ẹni ìparun.”

Verse 19

فَقَدْ كَذَّبُوكُم بِمَا تَقُولُونَ فَمَا تَسْتَطِيعُونَ صَرْفًا وَلَا نَصْرًا ۚ وَمَن يَظْلِم مِّنكُمْ نُذِقْهُ عَذَابًا كَبِيرًا

Transliteration faqad kadhabūkum bimā taqūlūna famā tastaṭīʿūna ṣarfan walā naṣran waman yaẓlim minkum nudhiq'hu ʿadhāban kabīran

Yoruba (Allāhu sọ pé): “Dájúdájú àwọn òrìṣà ti pe ẹ̀yin abọ̀rìṣà ní òpùrọ́ nípa ohun tí ẹ̀ ń sọ (pé olùṣìpẹ̀ ni wọ́n). Ní báyìí wọn kò lè gbé ìyà Iná kúrò fún yín, wọn kò sì lè ràn yín lọ́wọ́. Ẹnikẹ́ni tí ó ṣe àbòsí (ẹbọ ṣíṣe) nínú yín, A sì máa fún un ní ìyà tó tóbi tọ́ wò.”

Verse 20

وَمَآ أَرْسَلْنَا قَبْلَكَ مِنَ ٱلْمُرْسَلِينَ إِلَّآ إِنَّهُمْ لَيَأْكُلُونَ ٱلطَّعَامَ وَيَمْشُونَ فِى ٱلْأَسْوَاقِ ۗ وَجَعَلْنَا بَعْضَكُمْ لِبَعْضٍ فِتْنَةً أَتَصْبِرُونَ ۗ وَكَانَ رَبُّكَ بَصِيرًا

Transliteration wamā arsalnā qablaka mina l-mur'salīna illā innahum layakulūna l-ṭaʿāma wayamshūna fī l-aswāqi wajaʿalnā baʿḍakum libaʿḍin fit'natan ataṣbirūna wakāna rabbuka baṣīran

Yoruba A kò rán àwọn Òjíṣẹ́ níṣẹ́ rí ṣíwájú rẹ àfi kí wọ́n jẹun, kí wọ́n sì rìn nínú ọjà. A ti fi apá kan yín ṣe àdánwò fún apá kan, ǹjẹ́ ẹ máa ṣe sùúrù bí? Olúwa Rẹ sì ń jẹ́ Olùríran.

Verse 21

۞ وَقَالَ ٱلَّذِينَ لَا يَرْجُونَ لِقَآءَنَا لَوْلَآ أُنزِلَ عَلَيْنَا ٱلْمَلَـٰٓئِكَةُ أَوْ نَرَىٰ رَبَّنَا ۗ لَقَدِ ٱسْتَكْبَرُوا۟ فِىٓ أَنفُسِهِمْ وَعَتَوْ عُتُوًّا كَبِيرًا

Transliteration waqāla alladhīna lā yarjūna liqāanā lawlā unzila ʿalaynā l-malāikatu aw narā rabbanā laqadi is'takbarū fī anfusihim waʿataw ʿutuwwan kabīran

Yoruba Àwọn tí kò retí ìpàdé Wa (ní ọ̀run) wí pé: “Wọn kò ṣe sọ àwọn mọlāika kalẹ̀ fún wa tàbí kí á rí Olúwa wa (ní ojúkojú)? Dájúdájú wọ́n ti ṣègbéraga nínú ẹ̀mí wọn. Wọ́n sì ti tayọ ẹnu-ààlà ní ìtayọ ẹnu-ààlà tó tóbi.

Verse 22

يَوْمَ يَرَوْنَ ٱلْمَلَـٰٓئِكَةَ لَا بُشْرَىٰ يَوْمَئِذٍ لِّلْمُجْرِمِينَ وَيَقُولُونَ حِجْرًا مَّحْجُورًا

Transliteration yawma yarawna l-malāikata lā bush'rā yawma-idhin lil'muj'rimīna wayaqūlūna ḥij'ran maḥjūran

Yoruba (Rántí) ọjọ́ tí wọ́n yóò rí àwọn mọlāika, kò níí sí ìró ìdùnnú fún àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ní ọjọ́ yẹn. (Àwọn mọlāika) yó sì sọ pé: “Èèwọ̀, èèwọ̀ (ni ìró ìdùnnú fún ẹ̀yin ẹlẹ́ṣẹ̀).”

Verse 23

وَقَدِمْنَآ إِلَىٰ مَا عَمِلُوا۟ مِنْ عَمَلٍ فَجَعَلْنَـٰهُ هَبَآءً مَّنثُورًا

Transliteration waqadim'nā ilā mā ʿamilū min ʿamalin fajaʿalnāhu habāan manthūran

Yoruba Àti pé A máa wá ṣíbi ohun tí wọ́n ṣe níṣẹ́, A sì máa sọ ọ́ di eruku tí wọ́n fẹ́ dànù.

Verse 24

أَصْحَـٰبُ ٱلْجَنَّةِ يَوْمَئِذٍ خَيْرٌ مُّسْتَقَرًّا وَأَحْسَنُ مَقِيلًا

Transliteration aṣḥābu l-janati yawma-idhin khayrun mus'taqarran wa-aḥsanu maqīlan

Yoruba Àwọn èrò inú Ọgbà Ìdẹ̀ra, ní ọjọ́ yẹn, (ọgbà wọn) máa lóore jùlọ ní ibùgbé. Ó sì máa dára jùlọ ní ibùsinmi.

Verse 25

وَيَوْمَ تَشَقَّقُ ٱلسَّمَآءُ بِٱلْغَمَـٰمِ وَنُزِّلَ ٱلْمَلَـٰٓئِكَةُ تَنزِيلًا

Transliteration wayawma tashaqqaqu l-samāu bil-ghamāmi wanuzzila l-malāikatu tanzīlan

Yoruba Àti pé (rántí) ọjọ́ tí sánmọ̀ yó fàya pẹ́rẹpẹ̀rẹ pẹ̀lú àwọn ẹ̀ṣújò funfun (tí yóò máa tú jáde nínú wọn).A sì máa sọ àwọn mọlāika kalẹ̀ tààrà.

Verse 26

ٱلْمُلْكُ يَوْمَئِذٍ ٱلْحَقُّ لِلرَّحْمَـٰنِ ۚ وَكَانَ يَوْمًا عَلَى ٱلْكَـٰفِرِينَ عَسِيرًا

Transliteration al-mul'ku yawma-idhin l-ḥaqu lilrraḥmāni wakāna yawman ʿalā l-kāfirīna ʿasīran

Yoruba Ìjọba òdodo ti ọjọ́ yẹn ń jẹ́ ti Àjọkẹ́-ayé. Ó sì jẹ́ ọjọ́ kan tí ó máa nira fún àwọn aláìgbàgbọ́.

Verse 27

وَيَوْمَ يَعَضُّ ٱلظَّالِمُ عَلَىٰ يَدَيْهِ يَقُولُ يَـٰلَيْتَنِى ٱتَّخَذْتُ مَعَ ٱلرَّسُولِ سَبِيلًا

Transliteration wayawma yaʿaḍḍu l-ẓālimu ʿalā yadayhi yaqūlu yālaytanī ittakhadhtu maʿa l-rasūli sabīlan

Yoruba (Rántí) ọjọ́ tí alábòsí yóò jẹ ìka ọwọ́ rẹ̀ méjèèjì, ó sì máa wí pé: “Yéè! Èmi ìbá ti tọ ọ̀nà kan (náà) pẹ̀lú Òjíṣẹ́ náà.

Verse 28

يَـٰوَيْلَتَىٰ لَيْتَنِى لَمْ أَتَّخِذْ فُلَانًا خَلِيلًا

Transliteration yāwaylatā laytanī lam attakhidh fulānan khalīlan

Yoruba Ègbé mi o, yéè! Èmi ìbá tí mú lágbájá ní ọ̀rẹ́ àyò.

Verse 29

لَّقَدْ أَضَلَّنِى عَنِ ٱلذِّكْرِ بَعْدَ إِذْ جَآءَنِى ۗ وَكَانَ ٱلشَّيْطَـٰنُ لِلْإِنسَـٰنِ خَذُولًا

Transliteration laqad aḍallanī ʿani l-dhik'ri baʿda idh jāanī wakāna l-shayṭānu lil'insāni khadhūlan

Yoruba Dájúdájú ó ti ṣì mí lọ́nà kúrò níbi Ìrántí lẹ́yìn tí ó dé bá mi. Dájúdájú Èṣù ń jẹ́ adáni-dáṣòro fún ọmọnìyàn.”

Verse 30

وَقَالَ ٱلرَّسُولُ يَـٰرَبِّ إِنَّ قَوْمِى ٱتَّخَذُوا۟ هَـٰذَا ٱلْقُرْءَانَ مَهْجُورًا

Transliteration waqāla l-rasūlu yārabbi inna qawmī ittakhadhū hādhā l-qur'āna mahjūran

Yoruba Òjíṣẹ́ náà sọ pé: “Olúwa mi dájúdájú àwọn ènìyàn mi tí pa al-Ƙur’ān yìí tì.”

Verse 31

وَكَذَٰلِكَ جَعَلْنَا لِكُلِّ نَبِىٍّ عَدُوًّا مِّنَ ٱلْمُجْرِمِينَ ۗ وَكَفَىٰ بِرَبِّكَ هَادِيًا وَنَصِيرًا

Transliteration wakadhālika jaʿalnā likulli nabiyyin ʿaduwwan mina l-muj'rimīna wakafā birabbika hādiyan wanaṣīran

Yoruba Báyẹn ni A ṣe àwọn kan nínú àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ní ọ̀tá fún Ànábì kọ̀ọ̀kan. Olúwa rẹ sì tó ní Afinimọ̀nà àti Alárànṣe.

Verse 32

وَقَالَ ٱلَّذِينَ كَفَرُوا۟ لَوْلَا نُزِّلَ عَلَيْهِ ٱلْقُرْءَانُ جُمْلَةً وَٰحِدَةً ۚ كَذَٰلِكَ لِنُثَبِّتَ بِهِۦ فُؤَادَكَ ۖ وَرَتَّلْنَـٰهُ تَرْتِيلًا

Transliteration waqāla alladhīna kafarū lawlā nuzzila ʿalayhi l-qur'ānu jum'latan wāḥidatan kadhālika linuthabbita bihi fuādaka warattalnāhu tartīlan

Yoruba Àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ wí pé: “Wọn kò ṣe sọ al-Ƙur’ān kalẹ̀ fún un ní àpapọ̀ ní ẹ̀ẹ̀ kan náà?” (A sọ̀ ọ́ kalẹ̀ díẹ̀díẹ̀) báyẹn nítorí kí A lè fi rinlẹ̀ sínú ọkàn rẹ. A sì ké e fún ọ díẹ̀díẹ̀.

Verse 33

وَلَا يَأْتُونَكَ بِمَثَلٍ إِلَّا جِئْنَـٰكَ بِٱلْحَقِّ وَأَحْسَنَ تَفْسِيرًا

Transliteration walā yatūnaka bimathalin illā ji'nāka bil-ḥaqi wa-aḥsana tafsīran

Yoruba Wọn kò níí mú àpẹ̀ẹrẹ kan wá fún ọ (gẹ́gẹ́ bí ìbéèrè láti fi takò ọ́) àfi kí Á mú òdodo (ìyẹn, al-ƙur’ān) àti àlàyé tó dára jùlọ wá fún ọ (lórí rẹ̀).

Verse 34

ٱلَّذِينَ يُحْشَرُونَ عَلَىٰ وُجُوهِهِمْ إِلَىٰ جَهَنَّمَ أُو۟لَـٰٓئِكَ شَرٌّ مَّكَانًا وَأَضَلُّ سَبِيلًا

Transliteration alladhīna yuḥ'sharūna ʿalā wujūhihim ilā jahannama ulāika sharrun makānan wa-aḍallu sabīlan

Yoruba Àwọn tí A máa kó jọ lọ sínú iná Jahanamọ ní ìdojúbolẹ̀, àwọn wọ̀nyẹn ni àyè wọn burú jùlọ. Wọ́n sì ṣìnà jùlọ.

Verse 35

وَلَقَدْ ءَاتَيْنَا مُوسَى ٱلْكِتَـٰبَ وَجَعَلْنَا مَعَهُۥٓ أَخَاهُ هَـٰرُونَ وَزِيرًا

Transliteration walaqad ātaynā mūsā l-kitāba wajaʿalnā maʿahu akhāhu hārūna wazīran

Yoruba Dájúdájú A fún (Ànábì) Mūsā ní Tírà. A tún ṣe arákùnrin rẹ̀, Hārūn, ní amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ fún un.

Verse 36

فَقُلْنَا ٱذْهَبَآ إِلَى ٱلْقَوْمِ ٱلَّذِينَ كَذَّبُوا۟ بِـَٔايَـٰتِنَا فَدَمَّرْنَـٰهُمْ تَدْمِيرًا

Transliteration faqul'nā idh'habā ilā l-qawmi alladhīna kadhabū biāyātinā fadammarnāhum tadmīran

Yoruba A sì sọ pé: “Ẹ̀yin méjèèjì, ẹ lọ sọ́dọ̀ ìjọ tó pe àwọn āyah Wa nírọ́. A sì pa ìjọ náà run pátápátá.

Verse 37

وَقَوْمَ نُوحٍ لَّمَّا كَذَّبُوا۟ ٱلرُّسُلَ أَغْرَقْنَـٰهُمْ وَجَعَلْنَـٰهُمْ لِلنَّاسِ ءَايَةً ۖ وَأَعْتَدْنَا لِلظَّـٰلِمِينَ عَذَابًا أَلِيمًا

Transliteration waqawma nūḥin lammā kadhabū l-rusula aghraqnāhum wajaʿalnāhum lilnnāsi āyatan wa-aʿtadnā lilẓẓālimīna ʿadhāban alīman

Yoruba (Rántí) ìjọ (Ànábì) Nūh. Nígbà tí wọ́n pe àwọn Òjíṣẹ́ ní òpùrọ́, A tẹ̀ wọ́n rì sínú omi. A sì ṣe wọ́n ní àmì kan fún àwọn ènìyàn. A sì ti pèsè ìyà ẹlẹ́ta-eléro sílẹ̀ de àwọn alábòsí.

Verse 38

وَعَادًا وَثَمُودَا۟ وَأَصْحَـٰبَ ٱلرَّسِّ وَقُرُونًۢا بَيْنَ ذَٰلِكَ كَثِيرًا

Transliteration waʿādan wathamūdā wa-aṣḥāba l-rasi waqurūnan bayna dhālika kathīran

Yoruba (Rántí) àwọn ìjọ ‘Ād, ìjọ Thamūd, ìjọ Rass àti àwọn ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ìran mìíràn (tó ń bẹ) láààrin wọn.

Verse 39

وَكُلًّا ضَرَبْنَا لَهُ ٱلْأَمْثَـٰلَ ۖ وَكُلًّا تَبَّرْنَا تَتْبِيرًا

Transliteration wakullan ḍarabnā lahu l-amthāla wakullan tabbarnā tatbīran

Yoruba Ìkọ̀ọ̀kan wọn ni A fún ní àwọn àpẹ̀ẹrẹ (gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí àti àlàyé ọ̀rọ̀). Ìkọ̀ọ̀kan wọn sì ni A parun pátápátá (torí àìgbàgbọ́ wọn).

Verse 40

وَلَقَدْ أَتَوْا۟ عَلَى ٱلْقَرْيَةِ ٱلَّتِىٓ أُمْطِرَتْ مَطَرَ ٱلسَّوْءِ ۚ أَفَلَمْ يَكُونُوا۟ يَرَوْنَهَا ۚ بَلْ كَانُوا۟ لَا يَرْجُونَ نُشُورًا

Transliteration walaqad ataw ʿalā l-qaryati allatī um'ṭirat maṭara l-sawi afalam yakūnū yarawnahā bal kānū lā yarjūna nushūran

Yoruba Àti pé dájúdájú àwọn náà kọjá ní ìlú tí A rọ òjò burúkú lé lórí. Ṣé wọn kì í rí i ni? Rárá, ńṣe ni wọn kò retí Àjíǹde.

Verse 41

وَإِذَا رَأَوْكَ إِن يَتَّخِذُونَكَ إِلَّا هُزُوًا أَهَـٰذَا ٱلَّذِى بَعَثَ ٱللَّهُ رَسُولًا

Transliteration wa-idhā ra-awka in yattakhidhūnaka illā huzuwan ahādhā alladhī baʿatha l-lahu rasūlan

Yoruba Nígbà tí wọ́n bá sì rí ọ, kò sí ohun tí wọn yóò fi ọ́ ṣe bí kò ṣe yẹ̀yẹ́. (Wọ́n á wí pé): “Ṣé èyí ni ẹni tí Allāhu gbé dìde ní Òjíṣẹ́!?

Verse 42

إِن كَادَ لَيُضِلُّنَا عَنْ ءَالِهَتِنَا لَوْلَآ أَن صَبَرْنَا عَلَيْهَا ۚ وَسَوْفَ يَعْلَمُونَ حِينَ يَرَوْنَ ٱلْعَذَابَ مَنْ أَضَلُّ سَبِيلًا

Transliteration in kāda layuḍillunā ʿan ālihatinā lawlā an ṣabarnā ʿalayhā wasawfa yaʿlamūna ḥīna yarawna l-ʿadhāba man aḍallu sabīlan

Yoruba Ó mà fẹ́ẹ̀ ṣẹ́rí wa kúrò níbi àwọn ọlọ́hun wa, tí kì í bá ṣe pé a takú sorí rẹ̀.” Láìpẹ́ wọn máa mọ ẹni tí ó ṣìnà jùlọ nígbà tí wọ́n bá rí ìyà.

Verse 43

أَرَءَيْتَ مَنِ ٱتَّخَذَ إِلَـٰهَهُۥ هَوَىٰهُ أَفَأَنتَ تَكُونُ عَلَيْهِ وَكِيلًا

Transliteration ara-ayta mani ittakhadha ilāhahu hawāhu afa-anta takūnu ʿalayhi wakīlan

Yoruba Sọ fún mi nípa ẹni tí ó sọ ìfẹ́-inú rẹ̀ di ọlọ́hun rẹ̀! Nítorí náà, ṣé ìwọ máa jẹ́ aláàbò fún un ni (níbi ìyà)?

Verse 44

أَمْ تَحْسَبُ أَنَّ أَكْثَرَهُمْ يَسْمَعُونَ أَوْ يَعْقِلُونَ ۚ إِنْ هُمْ إِلَّا كَٱلْأَنْعَـٰمِ ۖ بَلْ هُمْ أَضَلُّ سَبِيلًا

Transliteration am taḥsabu anna aktharahum yasmaʿūna aw yaʿqilūna in hum illā kal-anʿāmi bal hum aḍallu sabīlan

Yoruba Tàbí ìwọ ń rò pé dájúdájú ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn ń gbọ́ràn tàbí pé wọ́n ń ṣe làákàyè? Kí ni wọ́n ná, bí kò ṣe bí àgùtàn. Rárá, wọ́n ṣìnà jùlọ.

Verse 45

أَلَمْ تَرَ إِلَىٰ رَبِّكَ كَيْفَ مَدَّ ٱلظِّلَّ وَلَوْ شَآءَ لَجَعَلَهُۥ سَاكِنًا ثُمَّ جَعَلْنَا ٱلشَّمْسَ عَلَيْهِ دَلِيلًا

Transliteration alam tara ilā rabbika kayfa madda l-ẓila walaw shāa lajaʿalahu sākinan thumma jaʿalnā l-shamsa ʿalayhi dalīlan

Yoruba Ṣé o ò rí (iṣẹ́) Olúwa rẹ ni, bí Ó ṣe fẹ òkùnkùn òwúrọ̀ lójú (sójú sánmọ̀)? Tí Ó bá fẹ́ ni, ìbá dá a dúró síbẹ̀. Lẹ́yìn náà, A fi òòrùn ṣe atọ́ka sí bíbẹ òkùnkùn.

Verse 46

ثُمَّ قَبَضْنَـٰهُ إِلَيْنَا قَبْضًا يَسِيرًا

Transliteration thumma qabaḍnāhu ilaynā qabḍan yasīran

Yoruba Lẹ́yìn náà, A (fi ìmọ́lẹ̀ òòrùn) mú òkùnkùn (kúrò níta) wá sí ọ̀dọ̀ Wa ní mímú díẹ̀díẹ̀ (kí ojúmọ́ lè mọ́).

Verse 47

وَهُوَ ٱلَّذِى جَعَلَ لَكُمُ ٱلَّيْلَ لِبَاسًا وَٱلنَّوْمَ سُبَاتًا وَجَعَلَ ٱلنَّهَارَ نُشُورًا

Transliteration wahuwa alladhī jaʿala lakumu al-layla libāsan wal-nawma subātan wajaʿala l-nahāra nushūran

Yoruba Àti pé Òun ni Ẹni tí Ó ṣe òru ní ìbora fún yín. (Ó ṣe) oorun ní ìsinmi (fún yín). Ó tún ṣe ọ̀sán ní àsìkò ìtúsíta (fún wíwá ìjẹ-ìmu).

Verse 48

وَهُوَ ٱلَّذِىٓ أَرْسَلَ ٱلرِّيَـٰحَ بُشْرًۢا بَيْنَ يَدَىْ رَحْمَتِهِۦ ۚ وَأَنزَلْنَا مِنَ ٱلسَّمَآءِ مَآءً طَهُورًا

Transliteration wahuwa alladhī arsala l-riyāḥa bush'ran bayna yaday raḥmatihi wa-anzalnā mina l-samāi māan ṭahūran

Yoruba Òun sì ni Ẹni t’Ó ń rán atẹ́gùn ní ìró-ìdùnnú ṣíwájú ìkẹ́ Rẹ̀. A sì sọ omi mímọ́ kalẹ̀ láti sánmọ̀

Verse 49

لِّنُحْـِۧىَ بِهِۦ بَلْدَةً مَّيْتًا وَنُسْقِيَهُۥ مِمَّا خَلَقْنَآ أَنْعَـٰمًا وَأَنَاسِىَّ كَثِيرًا

Transliteration linuḥ'yiya bihi baldatan maytan wanus'qiyahu mimmā khalaqnā anʿāman wa-anāsiyya kathīran

Yoruba nítorí kí A lè fi sọ òkú ilẹ̀ di àyè ilẹ̀ àti nítorí kí A lè fún ẹran-ọ̀sìn àti ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ènìyàn nínú àwọn tí A dá ní omi mu.

Verse 50

وَلَقَدْ صَرَّفْنَـٰهُ بَيْنَهُمْ لِيَذَّكَّرُوا۟ فَأَبَىٰٓ أَكْثَرُ ٱلنَّاسِ إِلَّا كُفُورًا

Transliteration walaqad ṣarrafnāhu baynahum liyadhakkarū fa-abā aktharu l-nāsi illā kufūran

Yoruba Dájúdájú À ń darí omi yìí káàkiri láààrin wọnnítorí kí wọ́n lè rántí (ìkẹ́ Olúwa wọn). Ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ènìyàn kọ̀ (láti rántí) àfi àìmoore.

Verse 51

وَلَوْ شِئْنَا لَبَعَثْنَا فِى كُلِّ قَرْيَةٍ نَّذِيرًا

Transliteration walaw shi'nā labaʿathnā fī kulli qaryatin nadhīran

Yoruba Tí ó bá jẹ́ pé A bá fẹ́ ni, A ìbá gbé olùkìlọ̀ kan dìde nínú ìlú kọ̀ọ̀kan.1

Verse 52

فَلَا تُطِعِ ٱلْكَـٰفِرِينَ وَجَـٰهِدْهُم بِهِۦ جِهَادًا كَبِيرًا

Transliteration falā tuṭiʿi l-kāfirīna wajāhid'hum bihi jihādan kabīran

Yoruba Nítorí náà, má ṣe tẹ̀lé àwọn aláìgbàgbọ́. Kí o sì fi (al-Ƙur’ān) jà wọ́n ní ogun tó tóbi.

Verse 53

۞ وَهُوَ ٱلَّذِى مَرَجَ ٱلْبَحْرَيْنِ هَـٰذَا عَذْبٌ فُرَاتٌ وَهَـٰذَا مِلْحٌ أُجَاجٌ وَجَعَلَ بَيْنَهُمَا بَرْزَخًا وَحِجْرًا مَّحْجُورًا

Transliteration wahuwa alladhī maraja l-baḥrayni hādhā ʿadhbun furātun wahādhā mil'ḥun ujājun wajaʿala baynahumā barzakhan waḥij'ran maḥjūran

Yoruba Òun ni Ẹni tí Ó mú àwọn odò méjì ṣàn kiri. Èyí (ni omi) tó dùn gan-an. Èyí sì (ni omi) iyọ̀ tó móró. Ó sì fi gàgá sí ààrin àwọn méjèèjì. (Ó sì) ṣe é ní èèwọ̀ pọ́nńbélé (fún wọn láti kó ìnira bá ẹ̀dá).

Verse 54

وَهُوَ ٱلَّذِى خَلَقَ مِنَ ٱلْمَآءِ بَشَرًا فَجَعَلَهُۥ نَسَبًا وَصِهْرًا ۗ وَكَانَ رَبُّكَ قَدِيرًا

Transliteration wahuwa alladhī khalaqa mina l-māi basharan fajaʿalahu nasaban waṣih'ran wakāna rabbuka qadīran

Yoruba Òun ni Ẹni tí Ó ṣẹ̀dá abara láti inú omi. Ó ṣe ìbátan ẹbí àti ìbátan àna fún un, Olúwa rẹ sì ń jẹ́ Alágbára.1

Verse 55

وَيَعْبُدُونَ مِن دُونِ ٱللَّهِ مَا لَا يَنفَعُهُمْ وَلَا يَضُرُّهُمْ ۗ وَكَانَ ٱلْكَافِرُ عَلَىٰ رَبِّهِۦ ظَهِيرًا

Transliteration wayaʿbudūna min dūni l-lahi mā lā yanfaʿuhum walā yaḍurruhum wakāna l-kāfiru ʿalā rabbihi ẓahīran

Yoruba Wọ́n ń jọ́sìn fún lẹ́yìn Allāhu ohun tí kò lè ṣe wọ́n ní àǹfààní, tí kò sì lè kó ìnira bá wọn. Aláìgbàgbọ́ jẹ́ olùrànlọ́wọ́ (fún Èṣù) láti tako Olúwa rẹ̀.

Verse 56

وَمَآ أَرْسَلْنَـٰكَ إِلَّا مُبَشِّرًا وَنَذِيرًا

Transliteration wamā arsalnāka illā mubashiran wanadhīran

Yoruba A kò sì rán ọ níṣẹ́ tayọ kí o jẹ́ oníròó-ìdùnnú àti olùkìlọ̀.

Verse 57

قُلْ مَآ أَسْـَٔلُكُمْ عَلَيْهِ مِنْ أَجْرٍ إِلَّا مَن شَآءَ أَن يَتَّخِذَ إِلَىٰ رَبِّهِۦ سَبِيلًا

Transliteration qul mā asalukum ʿalayhi min ajrin illā man shāa an yattakhidha ilā rabbihi sabīlan

Yoruba Sọ pé: “Èmi kò bèèrè owó-ọ̀yà kan lọ́wọ́ yín lórí rẹ̀ àfi ẹni tí ó bá fẹ́ mú ọ̀nà (dáadáa) tọ̀ lọ sí ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ̀.”1

Verse 58

وَتَوَكَّلْ عَلَى ٱلْحَىِّ ٱلَّذِى لَا يَمُوتُ وَسَبِّحْ بِحَمْدِهِۦ ۚ وَكَفَىٰ بِهِۦ بِذُنُوبِ عِبَادِهِۦ خَبِيرًا

Transliteration watawakkal ʿalā l-ḥayi alladhī lā yamūtu wasabbiḥ biḥamdihi wakafā bihi bidhunūbi ʿibādihi khabīran

Yoruba Gbáralé Alààyè tí kò níí kú. Ṣe àfọ̀mọ́ pẹ̀lú ẹyìn fún Un.Allāhu sì tó ní Alámọ̀tán nípa ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ẹrúsìn Rẹ̀.

Verse 59

ٱلَّذِى خَلَقَ ٱلسَّمَـٰوَٰتِ وَٱلْأَرْضَ وَمَا بَيْنَهُمَا فِى سِتَّةِ أَيَّامٍ ثُمَّ ٱسْتَوَىٰ عَلَى ٱلْعَرْشِ ۚ ٱلرَّحْمَـٰنُ فَسْـَٔلْ بِهِۦ خَبِيرًا

Transliteration alladhī khalaqa l-samāwāti wal-arḍa wamā baynahumā fī sittati ayyāmin thumma is'tawā ʿalā l-ʿarshi l-raḥmānu fasal bihi khabīran

Yoruba (Òun ni) Ẹni tí Ó ṣẹ̀dá àwọn sánmọ̀, ilẹ̀ àti àwọn n̄ǹkan tó ń bẹ láààrin méjèèjì láààrin ọjọ́ mẹ́fà. Lẹ́yìn náà, Ó gúnwà sórí Ìtẹ́-ọlá. Àjọkẹ́-ayé ni, nítorí náà, bèèrè nípa Rẹ̀ (lọ́dọ̀ Rẹ̀ nítorí pé, Ó jẹ́) Alámọ̀tán.

Verse 60

وَإِذَا قِيلَ لَهُمُ ٱسْجُدُوا۟ لِلرَّحْمَـٰنِ قَالُوا۟ وَمَا ٱلرَّحْمَـٰنُ أَنَسْجُدُ لِمَا تَأْمُرُنَا وَزَادَهُمْ نُفُورًا ۩

Transliteration wa-idhā qīla lahumu us'judū lilrraḥmāni qālū wamā l-raḥmānu anasjudu limā tamurunā wazādahum nufūran

Yoruba Nígbà tí wọ́n bá sọ fún wọn pé: “Ẹ forí kanlẹ̀ fún Àjọkẹ́-ayé.” Wọ́n á wí pé: “Kí ni Àjọkẹ-ayé? Ṣé kí á forí kanlẹ̀ fún ohun tí ò ń pa wá láṣẹ rẹ̀ ni?” (Ìpèpè náà) sì mú wọn lékún ní sísá-sẹ́yìn.

Verse 61

تَبَارَكَ ٱلَّذِى جَعَلَ فِى ٱلسَّمَآءِ بُرُوجًا وَجَعَلَ فِيهَا سِرَٰجًا وَقَمَرًا مُّنِيرًا

Transliteration tabāraka alladhī jaʿala fī l-samāi burūjan wajaʿala fīhā sirājan waqamaran munīran

Yoruba Ìbùkún ni fún Ẹni tí Ó ṣe àwọn ibùsọ̀ ìràwọ̀ sínú sánmọ̀. Ó tún ṣe òòrùn àti òṣùpá ní ìmọ́lẹ̀ sínú rẹ̀.

Verse 62

وَهُوَ ٱلَّذِى جَعَلَ ٱلَّيْلَ وَٱلنَّهَارَ خِلْفَةً لِّمَنْ أَرَادَ أَن يَذَّكَّرَ أَوْ أَرَادَ شُكُورًا

Transliteration wahuwa alladhī jaʿala al-layla wal-nahāra khil'fatan liman arāda an yadhakkara aw arāda shukūran

Yoruba Òun ni Ẹni tí Ó ṣe òru àti ọ̀sán ní ìtẹ̀léǹtẹ̀lé (tí ìkíní yàtọ̀ sí ìkejì) nítorí ẹni tí ó bá gbèrò láti ṣe ìrántí (Allāhu) tàbí tí ó bá gbèrò ìdúpẹ́ (fún Un).

Verse 63

وَعِبَادُ ٱلرَّحْمَـٰنِ ٱلَّذِينَ يَمْشُونَ عَلَى ٱلْأَرْضِ هَوْنًا وَإِذَا خَاطَبَهُمُ ٱلْجَـٰهِلُونَ قَالُوا۟ سَلَـٰمًا

Transliteration waʿibādu l-raḥmāni alladhīna yamshūna ʿalā l-arḍi hawnan wa-idhā khāṭabahumu l-jāhilūna qālū salāman

Yoruba Àwọn ẹrúsìn Àjọkẹ́-ayé ni àwọn tó ń rìn jẹ́ẹ́jẹ́ lórí ilẹ̀. Nígbà tí àwọn òpè bá sì dojú ọ̀rọ̀ kọ wọ́n, wọn yóò sọ ọ̀rọ̀ àlàáfíà.

Verse 64

وَٱلَّذِينَ يَبِيتُونَ لِرَبِّهِمْ سُجَّدًا وَقِيَـٰمًا

Transliteration wa-alladhīna yabītūna lirabbihim sujjadan waqiyāman

Yoruba (Àwọn ni) àwọn tó ń lo òru wọn ní ìforíkanlẹ̀ àti ní ìdúró-kírun fún Olúwa wọn.

Verse 65

وَٱلَّذِينَ يَقُولُونَ رَبَّنَا ٱصْرِفْ عَنَّا عَذَابَ جَهَنَّمَ ۖ إِنَّ عَذَابَهَا كَانَ غَرَامًا

Transliteration wa-alladhīna yaqūlūna rabbanā iṣ'rif ʿannā ʿadhāba jahannama inna ʿadhābahā kāna gharāman

Yoruba (Àwọn ni) àwọn tó ń sọ pé: “Olúwa wa, gbé ìyà iná Jahanamọ kúrò fún wa. Dájúdájú ìyà rẹ̀ jẹ́ ìyà àìnípẹ̀kun.

Verse 66

إِنَّهَا سَآءَتْ مُسْتَقَرًّا وَمُقَامًا

Transliteration innahā sāat mus'taqarran wamuqāman

Yoruba Dájúdájú ó burú ní ibùgbé àti ibùdúró.

Verse 67

وَٱلَّذِينَ إِذَآ أَنفَقُوا۟ لَمْ يُسْرِفُوا۟ وَلَمْ يَقْتُرُوا۟ وَكَانَ بَيْنَ ذَٰلِكَ قَوَامًا

Transliteration wa-alladhīna idhā anfaqū lam yus'rifū walam yaqturū wakāna bayna dhālika qawāman

Yoruba Àwọn tí ó jẹ́ pé nígbà tí wọ́n bá náwó, wọn kò ná ìná-àpà, wọn kò sì ṣahun; (ìnáwó wọn) wà láààrin ìyẹn ní ìwọ̀ntún-wọ̀nsì.

Verse 68

وَٱلَّذِينَ لَا يَدْعُونَ مَعَ ٱللَّهِ إِلَـٰهًا ءَاخَرَ وَلَا يَقْتُلُونَ ٱلنَّفْسَ ٱلَّتِى حَرَّمَ ٱللَّهُ إِلَّا بِٱلْحَقِّ وَلَا يَزْنُونَ ۚ وَمَن يَفْعَلْ ذَٰلِكَ يَلْقَ أَثَامًا

Transliteration wa-alladhīna lā yadʿūna maʿa l-lahi ilāhan ākhara walā yaqtulūna l-nafsa allatī ḥarrama l-lahu illā bil-ḥaqi walā yaznūna waman yafʿal dhālika yalqa athāman

Yoruba (Àwọn ni) àwọn tí kò pe ọlọ́hun mìíràn mọ́ Allāhu. Wọn kò pa ẹ̀mí tí Allāhu ṣe (pípa rẹ̀) ní èèwọ̀ àfi ní ọ̀nà ẹ̀tọ́. Àti pé wọn kò ṣe zinā. Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe (aburú) yẹn, ó máa pàdé (ìyà) ẹ̀ṣẹ̀.

Verse 69

يُضَـٰعَفْ لَهُ ٱلْعَذَابُ يَوْمَ ٱلْقِيَـٰمَةِ وَيَخْلُدْ فِيهِۦ مُهَانًا

Transliteration yuḍāʿaf lahu l-ʿadhābu yawma l-qiyāmati wayakhlud fīhi muhānan

Yoruba A óò ṣe ìyà ní ìlọ́po fún un ní Ọjọ́ Àjíǹde. Ó sì máa ṣe gbére nínú rẹ̀ ní ẹni yẹpẹrẹ.

Verse 70

إِلَّا مَن تَابَ وَءَامَنَ وَعَمِلَ عَمَلًا صَـٰلِحًا فَأُو۟لَـٰٓئِكَ يُبَدِّلُ ٱللَّهُ سَيِّـَٔاتِهِمْ حَسَنَـٰتٍ ۗ وَكَانَ ٱللَّهُ غَفُورًا رَّحِيمًا

Transliteration illā man tāba waāmana waʿamila ʿamalan ṣāliḥan fa-ulāika yubaddilu l-lahu sayyiātihim ḥasanātin wakāna l-lahu ghafūran raḥīman

Yoruba Àfi ẹni tí ó bá ronú pìwàdà, tí ó gbàgbọ́ ní òdodo, tí ó sì ṣe iṣẹ́ rere. Àwọn wọ̀nyẹn ni Allāhu yóò fi iṣẹ́ rere rọ́pò iṣẹ́ aburú wọn (ìyẹn, nípa ìronúpìwàdà wọn). Allāhu sì ń jẹ́ Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.

Verse 71

وَمَن تَابَ وَعَمِلَ صَـٰلِحًا فَإِنَّهُۥ يَتُوبُ إِلَى ٱللَّهِ مَتَابًا

Transliteration waman tāba waʿamila ṣāliḥan fa-innahu yatūbu ilā l-lahi matāban

Yoruba Ẹnikẹ́ni tí ó bá ronú pìwàdà, tí ó sì ṣe iṣẹ́ rere, (kí ó mọ̀) pé dájúdájú ó ń ronú pìwàdà pátápátá sọ́dọ̀ Allāhu ni.

Verse 72

وَٱلَّذِينَ لَا يَشْهَدُونَ ٱلزُّورَ وَإِذَا مَرُّوا۟ بِٱللَّغْوِ مَرُّوا۟ كِرَامًا

Transliteration wa-alladhīna lā yashhadūna l-zūra wa-idhā marrū bil-laghwi marrū kirāman

Yoruba (Àwọn ni) àwọn tí kò jẹ́rìí èké. Tí wọ́n bá sì kọjá níbi ìbàjẹ́, wọ́n á kọjá pẹ̀lú àpọ́nlé.1

Verse 73

وَٱلَّذِينَ إِذَا ذُكِّرُوا۟ بِـَٔايَـٰتِ رَبِّهِمْ لَمْ يَخِرُّوا۟ عَلَيْهَا صُمًّا وَعُمْيَانًا

Transliteration wa-alladhīna idhā dhukkirū biāyāti rabbihim lam yakhirrū ʿalayhā ṣumman waʿum'yānan

Yoruba (Àwọn ni) àwọn tí ó jẹ́ pé tí wọ́n bá fi àwọn āyah Olúwa wọn ṣèrántí fún wọn, wọn kò dà lulẹ̀ bí adití àti afọ́jú.

Verse 74

وَٱلَّذِينَ يَقُولُونَ رَبَّنَا هَبْ لَنَا مِنْ أَزْوَٰجِنَا وَذُرِّيَّـٰتِنَا قُرَّةَ أَعْيُنٍ وَٱجْعَلْنَا لِلْمُتَّقِينَ إِمَامًا

Transliteration wa-alladhīna yaqūlūna rabbanā hab lanā min azwājinā wadhurriyyātinā qurrata aʿyunin wa-ij'ʿalnā lil'muttaqīna imāman

Yoruba (Àwọn ni) àwọn tó ń sọ pé: “Olúwa wa, ta wá ní ọrẹ ìtutù-ojú (ìdùnnú àti ayọ̀) láti ara àwọn ìyàwó wa àti àwọn ọmọ wa. Kí O sì ṣe wá ní aṣíwájú (àwòkọ́ṣe rere) fún àwọn olùbẹ̀rù (Rẹ).”

Verse 75

أُو۟لَـٰٓئِكَ يُجْزَوْنَ ٱلْغُرْفَةَ بِمَا صَبَرُوا۟ وَيُلَقَّوْنَ فِيهَا تَحِيَّةً وَسَلَـٰمًا

Transliteration ulāika yuj'zawna l-ghur'fata bimā ṣabarū wayulaqqawna fīhā taḥiyyatan wasalāman

Yoruba Àwọn wọ̀nyẹn, ipò gíga (nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra) ni A máa fi san wọ́n ní ẹ̀san nítorí pé, wọ́n ṣe sùúrù. Ìkíni àti sísálámọ̀ ni A óò fi máa pàdé wọn nínú rẹ̀.

Verse 76

خَـٰلِدِينَ فِيهَا ۚ حَسُنَتْ مُسْتَقَرًّا وَمُقَامًا

Transliteration khālidīna fīhā ḥasunat mus'taqarran wamuqāman

Yoruba Olúṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀. Ó dára ní ibùgbé àti ibùdúró.

Verse 77

قُلْ مَا يَعْبَؤُا۟ بِكُمْ رَبِّى لَوْلَا دُعَآؤُكُمْ ۖ فَقَدْ كَذَّبْتُمْ فَسَوْفَ يَكُونُ لِزَامًۢا

Transliteration qul mā yaʿba-u bikum rabbī lawlā duʿāukum faqad kadhabtum fasawfa yakūnu lizāman

Yoruba Sọ pé: “Olúwa mi kò kà yín kún tí kì í bá ṣe àdúà yín (àti ìjọ́sìn yín). Ẹ kúkú ti pe (àwọn āyah Rẹ̀) nírọ́. Láìpẹ́ ó sì máa di ìyà àìnípẹ̀kun (fún yín).”

Read Surah Al-Furqan in another language

All languages

All 114 surahs in Yoruba: the Qur’an in Yoruba.

Learn it in MyDugsi

Yoruba translation: Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni, from Quran.com. Transliteration: Quran.com. Recitation: Mishary Alafasy, from EveryAyah.com. MyDugsi is a learning aid, not a replacement for a qualified teacher.