MyDugsiStart learning

Surah Yusuf in Yoruba: translation and audio

Surah 12 · يوسف · Joseph · 111 verses

Surah Yusuf verse by verse: the Arabic with a recitation you can repeat, the transliteration, and the Yoruba translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni. For the meaning of every word, see Surah Yusuf word by word in English.

Verse 1

الٓر ۚ تِلْكَ ءَايَـٰتُ ٱلْكِتَـٰبِ ٱلْمُبِينِ

Transliteration alif-lam-ra til'ka āyātu l-kitābi l-mubīni

Yoruba ’Alif lām rọ̄. (Allāhu ló mọ ohun tí Ó gbàlérò pẹ̀lú àwọn háràfí náà.)Ìwọ̀nyí ni àwọn āyah Tírà tó yanjú ọ̀rọ̀ ẹ̀dá.

Verse 2

إِنَّآ أَنزَلْنَـٰهُ قُرْءَٰنًا عَرَبِيًّا لَّعَلَّكُمْ تَعْقِلُونَ

Transliteration innā anzalnāhu qur'ānan ʿarabiyyan laʿallakum taʿqilūna

Yoruba Dájúdájú Àwa sọ̀ ọ́ kalẹ̀ ní n̄ǹkan kíké ní èdè Lárúbáwá nítorí kí ẹ lè ṣe làákàyè.

Verse 3

نَحْنُ نَقُصُّ عَلَيْكَ أَحْسَنَ ٱلْقَصَصِ بِمَآ أَوْحَيْنَآ إِلَيْكَ هَـٰذَا ٱلْقُرْءَانَ وَإِن كُنتَ مِن قَبْلِهِۦ لَمِنَ ٱلْغَـٰفِلِينَ

Transliteration naḥnu naquṣṣu ʿalayka aḥsana l-qaṣaṣi bimā awḥaynā ilayka hādhā l-qur'āna wa-in kunta min qablihi lamina l-ghāfilīna

Yoruba Àwa ń sọ ìtàn tó dára jùlọ fún ọ pẹ̀lú ohun tí A fi ránṣẹ́ sí ọ (nínú ìmísí) al-Ƙur’ān yìí, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ṣíwájú ìmísí náà ìwọ wà lára àwọn tí kò nímọ̀ (nípa rẹ̀).

Verse 4

إِذْ قَالَ يُوسُفُ لِأَبِيهِ يَـٰٓأَبَتِ إِنِّى رَأَيْتُ أَحَدَ عَشَرَ كَوْكَبًا وَٱلشَّمْسَ وَٱلْقَمَرَ رَأَيْتُهُمْ لِى سَـٰجِدِينَ

Transliteration idh qāla yūsufu li-abīhi yāabati innī ra-aytu aḥada ʿashara kawkaban wal-shamsa wal-qamara ra-aytuhum lī sājidīna

Yoruba (Rántí) nígbà tí (Ànábì) Yūsuf sọ fún bàbá rẹ̀ pé: “Bàbá mi, dájúdájú èmi (lálàá) rí àwọn ìràwọ̀ mọ́kànlá, òòrùn àti òṣùpá. Mo rí wọn tí wọ́n forí kanlẹ̀ fún mi.”

Verse 5

قَالَ يَـٰبُنَىَّ لَا تَقْصُصْ رُءْيَاكَ عَلَىٰٓ إِخْوَتِكَ فَيَكِيدُوا۟ لَكَ كَيْدًا ۖ إِنَّ ٱلشَّيْطَـٰنَ لِلْإِنسَـٰنِ عَدُوٌّ مُّبِينٌ

Transliteration qāla yābunayya lā taqṣuṣ ru'yāka ʿalā ikh'watika fayakīdū laka kaydan inna l-shayṭāna lil'insāni ʿaduwwun mubīnun

Yoruba Ó sọ pé: “Ọmọ mi, má ṣe rọ́ àlá rẹ fún àwọn ọbàkan rẹ kí wọ́n má baà déte sí ọ. Dájúdájú Èṣù ni ọ̀tá pọ́nńbélé fún ènìyàn.

Verse 6

وَكَذَٰلِكَ يَجْتَبِيكَ رَبُّكَ وَيُعَلِّمُكَ مِن تَأْوِيلِ ٱلْأَحَادِيثِ وَيُتِمُّ نِعْمَتَهُۥ عَلَيْكَ وَعَلَىٰٓ ءَالِ يَعْقُوبَ كَمَآ أَتَمَّهَا عَلَىٰٓ أَبَوَيْكَ مِن قَبْلُ إِبْرَٰهِيمَ وَإِسْحَـٰقَ ۚ إِنَّ رَبَّكَ عَلِيمٌ حَكِيمٌ

Transliteration wakadhālika yajtabīka rabbuka wayuʿallimuka min tawīli l-aḥādīthi wayutimmu niʿ'matahu ʿalayka waʿalā āli yaʿqūba kamā atammahā ʿalā abawayka min qablu ib'rāhīma wa-is'ḥāqa inna rabbaka ʿalīmun ḥakīmun

Yoruba Báyẹn ni Olúwa rẹ yóò ṣe ṣà ọ́ lẹ́ṣà. Ó máa fi ìtúmọ̀ àlá mọ̀ ọ́. Ó sì máa pé ìdẹ̀ra Rẹ̀ fún ìwọ àti àwọn ẹbí Ya‘ƙūb, gẹ́gẹ́ bí Ó ṣe pé e ṣíwájú fún àwọn bàbá rẹ méjèèjì, (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm àti ’Ishāƙ. Dájúdájú Olúwa rẹ ni Onímọ̀, Ọlọ́gbọ́n.”

Verse 7

۞ لَّقَدْ كَانَ فِى يُوسُفَ وَإِخْوَتِهِۦٓ ءَايَـٰتٌ لِّلسَّآئِلِينَ

Transliteration laqad kāna fī yūsufa wa-ikh'watihi āyātun lilssāilīna

Yoruba Dájúdájú àwọn àmì (àríwòye) ń bẹ fún àwọn oníbèéèrè nípa (ìtàn Ànábì) Yūsuf àti àwọn ọbàkan rẹ̀.

Verse 8

إِذْ قَالُوا۟ لَيُوسُفُ وَأَخُوهُ أَحَبُّ إِلَىٰٓ أَبِينَا مِنَّا وَنَحْنُ عُصْبَةٌ إِنَّ أَبَانَا لَفِى ضَلَـٰلٍ مُّبِينٍ

Transliteration idh qālū layūsufu wa-akhūhu aḥabbu ilā abīnā minnā wanaḥnu ʿuṣ'batun inna abānā lafī ḍalālin mubīnin

Yoruba (Rántí) nígbà tí wọ́n sọ pé: “Dájúdájú Yūsuf àti ọmọ-ìyá rẹ̀ ni bàbá wa nífẹ̀ẹ́ sí ju àwa. Ọ̀pọ̀ ènìyàn sì ni àwa. Dájúdájú bàbá wa mà ti wà nínú àṣìṣe pọ́nńbélé.

Verse 9

ٱقْتُلُوا۟ يُوسُفَ أَوِ ٱطْرَحُوهُ أَرْضًا يَخْلُ لَكُمْ وَجْهُ أَبِيكُمْ وَتَكُونُوا۟ مِنۢ بَعْدِهِۦ قَوْمًا صَـٰلِحِينَ

Transliteration uq'tulū yūsufa awi iṭ'raḥūhu arḍan yakhlu lakum wajhu abīkum watakūnū min baʿdihi qawman ṣāliḥīna

Yoruba Ẹ pa Yūsuf tàbí kí ẹ lọ gbé e jùnù sí ilẹ̀ kan nítorí kí bàbá yín lè rójú gbọ́ tiyín. Ẹ sì máa di ènìyàn rere lẹ́yìn rẹ̀.”

Verse 10

قَالَ قَآئِلٌ مِّنْهُمْ لَا تَقْتُلُوا۟ يُوسُفَ وَأَلْقُوهُ فِى غَيَـٰبَتِ ٱلْجُبِّ يَلْتَقِطْهُ بَعْضُ ٱلسَّيَّارَةِ إِن كُنتُمْ فَـٰعِلِينَ

Transliteration qāla qāilun min'hum lā taqtulū yūsufa wa-alqūhu fī ghayābati l-jubi yaltaqiṭ'hu baʿḍu l-sayārati in kuntum fāʿilīna

Yoruba Òǹsọ̀rọ̀ kan nínú wọn sọ pé: “Ẹ má ṣe pa Yūsuf. Tí ó bá jẹ́ pé ẹ ṣá fẹ́ wá n̄ǹkan ṣe (sí ọ̀rọ̀ rẹ̀), ẹ gbé e jù sínú ìsàlẹ̀ẹ̀sàlẹ̀ kànǹga nítorí kí apá kan nínú àwọn onírìn-àjò lè he é lọ.”

Verse 11

قَالُوا۟ يَـٰٓأَبَانَا مَا لَكَ لَا تَأْمَ۫نَّا عَلَىٰ يُوسُفَ وَإِنَّا لَهُۥ لَنَـٰصِحُونَ

Transliteration qālū yāabānā mā laka lā tamannā ʿalā yūsufa wa-innā lahu lanāṣiḥūna

Yoruba Wọ́n sọ pé: “Bàbá wa, kí ni kò mú ọ fi ọkàn tán wa lórí Yūsuf. Dájúdájú àwa yóò máa tọ́jú rẹ̀ dáadáa.

Verse 12

أَرْسِلْهُ مَعَنَا غَدًا يَرْتَعْ وَيَلْعَبْ وَإِنَّا لَهُۥ لَحَـٰفِظُونَ

Transliteration arsil'hu maʿanā ghadan yartaʿ wayalʿab wa-innā lahu laḥāfiẓūna

Yoruba Jẹ́ kí ó bá wa lọ ní ọ̀la kí ó lè dára yá, kí ó sì lè ṣeré. Àti pé dájúdájú àwa yóò máa ṣọ́ ọ.”

Verse 13

قَالَ إِنِّى لَيَحْزُنُنِىٓ أَن تَذْهَبُوا۟ بِهِۦ وَأَخَافُ أَن يَأْكُلَهُ ٱلذِّئْبُ وَأَنتُمْ عَنْهُ غَـٰفِلُونَ

Transliteration qāla innī layaḥzununī an tadhhabū bihi wa-akhāfu an yakulahu l-dhi'bu wa-antum ʿanhu ghāfilūna

Yoruba Ó sọ pé: “Dájúdájú ó máa bà mí nínú jẹ́ pé kí ẹ mú u lọ. Mo sì ń páyà kí ìkokò má lọ pa á jẹ nígbà tí ẹ̀yin bá gbàgbé rẹ̀ (síbì kan).”

Verse 14

قَالُوا۟ لَئِنْ أَكَلَهُ ٱلذِّئْبُ وَنَحْنُ عُصْبَةٌ إِنَّآ إِذًا لَّخَـٰسِرُونَ

Transliteration qālū la-in akalahu l-dhi'bu wanaḥnu ʿuṣ'batun innā idhan lakhāsirūna

Yoruba Wọ́n sọ pé: “Tí ìkokò bá fi pa á jẹ, ọ̀pọ̀ ènìyàn sì ni wá, dájúdájú àwa nígbà náà ni ẹni òfò.”

Verse 15

فَلَمَّا ذَهَبُوا۟ بِهِۦ وَأَجْمَعُوٓا۟ أَن يَجْعَلُوهُ فِى غَيَـٰبَتِ ٱلْجُبِّ ۚ وَأَوْحَيْنَآ إِلَيْهِ لَتُنَبِّئَنَّهُم بِأَمْرِهِمْ هَـٰذَا وَهُمْ لَا يَشْعُرُونَ

Transliteration falammā dhahabū bihi wa-ajmaʿū an yajʿalūhu fī ghayābati l-jubi wa-awḥaynā ilayhi latunabbi-annahum bi-amrihim hādhā wahum lā yashʿurūna

Yoruba Nígbà tí wọ́n mú un lọ tán, wọ́n panupọ̀ pé kí àwọn jù ú sí ìsàlẹ̀ẹ̀sàlẹ̀ kànǹga. À si fí ìmísí ránṣẹ́ sí Yūsuf (níbẹ̀) pé: “Dájúdájú ìwọ yóò fún wọn ní ìró nípa ọ̀rọ̀ wọn yìí nígbà tí wọn kò níí fura.”

Verse 16

وَجَآءُوٓ أَبَاهُمْ عِشَآءً يَبْكُونَ

Transliteration wajāū abāhum ʿishāan yabkūna

Yoruba Wọ́n dé bá bàbá wọn ní àṣálẹ́, tí wọ́n ń sunkún.

Verse 17

قَالُوا۟ يَـٰٓأَبَانَآ إِنَّا ذَهَبْنَا نَسْتَبِقُ وَتَرَكْنَا يُوسُفَ عِندَ مَتَـٰعِنَا فَأَكَلَهُ ٱلذِّئْبُ ۖ وَمَآ أَنتَ بِمُؤْمِنٍ لَّنَا وَلَوْ كُنَّا صَـٰدِقِينَ

Transliteration qālū yāabānā innā dhahabnā nastabiqu wataraknā yūsufa ʿinda matāʿinā fa-akalahu l-dhi'bu wamā anta bimu'minin lanā walaw kunnā ṣādiqīna

Yoruba Wọ́n sọ pé: “Bàbá wa, àwa lọ díje eré sísá. A sì fi Yūsuf sílẹ̀ síbi àwọn ẹrù wa. Nígbà náà ni ìkokò pa á jẹ. Ìwọ kò sì níí gbà wá gbọ́, àwa ìbáà jẹ́ olódodo.”

Verse 18

وَجَآءُو عَلَىٰ قَمِيصِهِۦ بِدَمٍ كَذِبٍ ۚ قَالَ بَلْ سَوَّلَتْ لَكُمْ أَنفُسُكُمْ أَمْرًا ۖ فَصَبْرٌ جَمِيلٌ ۖ وَٱللَّهُ ٱلْمُسْتَعَانُ عَلَىٰ مَا تَصِفُونَ

Transliteration wajāū ʿalā qamīṣihi bidamin kadhibin qāla bal sawwalat lakum anfusukum amran faṣabrun jamīlun wal-lahu l-mus'taʿānu ʿalā mā taṣifūna

Yoruba Wọ́n dé pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀ irọ́ lára ẹ̀wù rẹ̀. (Ànábì Ya‘ƙūb) sọ pé: “Rárá o, ẹ̀mí yín ló ṣe ọ̀ràn kan lọ́ṣọ̀ọ́ fún yín. Nítorí náà, sùúrù abiyì (lọ̀rọ̀ mi kàn). Allāhu sì ni Ẹni tí à ń wá àánú Rẹ̀ lórí ohun tí ẹ̀ ń ròyìn (yìí).”

Verse 19

وَجَآءَتْ سَيَّارَةٌ فَأَرْسَلُوا۟ وَارِدَهُمْ فَأَدْلَىٰ دَلْوَهُۥ ۖ قَالَ يَـٰبُشْرَىٰ هَـٰذَا غُلَـٰمٌ ۚ وَأَسَرُّوهُ بِضَـٰعَةً ۚ وَٱللَّهُ عَلِيمٌۢ بِمَا يَعْمَلُونَ

Transliteration wajāat sayyāratun fa-arsalū wāridahum fa-adlā dalwahu qāla yābush'rā hādhā ghulāmun wa-asarrūhu biḍāʿatan wal-lahu ʿalīmun bimā yaʿmalūna

Yoruba Àwọn onírìn-àjò kan sì dé. Wọ́n rán apọnmi wọn (ní omi). Ó sì ju doro rẹ̀ sínú kànǹga. (Yūsuf sì dìrọ̀ mọ́ okùn doro bọ́ síta. Apọnmi sì) sọ pé: “Ire ìdùnnú rè é! Èyí ni ọmọdékùnrin.” Wọ́n sì fi pamọ́ fún títà (bí ọjà). Allāhu sì ni Onímọ̀ nípa ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́.

Verse 20

وَشَرَوْهُ بِثَمَنٍۭ بَخْسٍ دَرَٰهِمَ مَعْدُودَةٍ وَكَانُوا۟ فِيهِ مِنَ ٱلزَّٰهِدِينَ

Transliteration washarawhu bithamanin bakhsin darāhima maʿdūdatin wakānū fīhi mina l-zāhidīna

Yoruba Wọ́n tà á ní ẹ̀dínwó pẹ̀lú owó diriham tó níye. Wọ́n kò sì wowọ́ mọ́ ọn.1

Verse 21

وَقَالَ ٱلَّذِى ٱشْتَرَىٰهُ مِن مِّصْرَ لِٱمْرَأَتِهِۦٓ أَكْرِمِى مَثْوَىٰهُ عَسَىٰٓ أَن يَنفَعَنَآ أَوْ نَتَّخِذَهُۥ وَلَدًا ۚ وَكَذَٰلِكَ مَكَّنَّا لِيُوسُفَ فِى ٱلْأَرْضِ وَلِنُعَلِّمَهُۥ مِن تَأْوِيلِ ٱلْأَحَادِيثِ ۚ وَٱللَّهُ غَالِبٌ عَلَىٰٓ أَمْرِهِۦ وَلَـٰكِنَّ أَكْثَرَ ٱلنَّاسِ لَا يَعْلَمُونَ

Transliteration waqāla alladhī ish'tarāhu min miṣ'ra li-im'ra-atihi akrimī mathwāhu ʿasā an yanfaʿanā aw nattakhidhahu waladan wakadhālika makkannā liyūsufa fī l-arḍi walinuʿallimahu min tawīli l-aḥādīthi wal-lahu ghālibun ʿalā amrihi walākinna akthara l-nāsi lā yaʿlamūna

Yoruba Ẹni tí ó rà á ní (ìlú) Misrọ sọ fún aya rẹ̀ pé: “Ṣàpọ́nlé ibùgbé rẹ̀. Ó súnmọ́ kí ó wúlò fún wa tàbí kí á fi ṣọmọ.” Báyẹn ni A ṣe fi àyè gba Yūsuf lórí ilẹ̀. Àti pé kí Á tún lè fi ìtúmọ̀ àlá mọ̀ ọ́n. Allāhu ni Olùborí lórí àṣẹ Rẹ̀, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ènìyàn ni kò mọ̀.

Verse 22

وَلَمَّا بَلَغَ أَشُدَّهُۥٓ ءَاتَيْنَـٰهُ حُكْمًا وَعِلْمًا ۚ وَكَذَٰلِكَ نَجْزِى ٱلْمُحْسِنِينَ

Transliteration walammā balagha ashuddahu ātaynāhu ḥuk'man waʿil'man wakadhālika najzī l-muḥ'sinīna

Yoruba Nígbà tí ó sì dàgbà dáadáa, A fún un ní ọgbọ́n ìjìnlẹ̀ àti ìmọ̀. Báyẹn ni A ṣe ń san àwọn olùṣe-rere ní ẹ̀san rere.

Verse 23

وَرَٰوَدَتْهُ ٱلَّتِى هُوَ فِى بَيْتِهَا عَن نَّفْسِهِۦ وَغَلَّقَتِ ٱلْأَبْوَٰبَ وَقَالَتْ هَيْتَ لَكَ ۚ قَالَ مَعَاذَ ٱللَّهِ ۖ إِنَّهُۥ رَبِّىٓ أَحْسَنَ مَثْوَاىَ ۖ إِنَّهُۥ لَا يُفْلِحُ ٱلظَّـٰلِمُونَ

Transliteration warāwadathu allatī huwa fī baytihā ʿan nafsihi waghallaqati l-abwāba waqālat hayta laka qāla maʿādha l-lahi innahu rabbī aḥsana mathwāya innahu lā yuf'liḥu l-ẓālimūna

Yoruba Obìnrin tí Yūsuf wà nínú ilé rẹ̀ sì jírẹ̀ẹ́bẹ̀ fún eré ìfẹ́ lọ́dọ̀ rẹ̀. Ó sì ti àwọn ìlẹ̀kùn pa. Ó sọ pé: “Súnmọ́ mi.” (Yūsuf) sọ pé: “Mo sádi Allāhu. Dájúdájú ọkọ rẹ ni ọ̀gá mi. Ó sì ṣe ibùgbé mi dáadáa. Dájúdájú àwọn alábòsí kò níí jèrè.”

Verse 24

وَلَقَدْ هَمَّتْ بِهِۦ ۖ وَهَمَّ بِهَا لَوْلَآ أَن رَّءَا بُرْهَـٰنَ رَبِّهِۦ ۚ كَذَٰلِكَ لِنَصْرِفَ عَنْهُ ٱلسُّوٓءَ وَٱلْفَحْشَآءَ ۚ إِنَّهُۥ مِنْ عِبَادِنَا ٱلْمُخْلَصِينَ

Transliteration walaqad hammat bihi wahamma bihā lawlā an raā bur'hāna rabbihi kadhālika linaṣrifa ʿanhu l-sūa wal-faḥshāa innahu min ʿibādinā l-mukh'laṣīna

Yoruba (Obìnrin náà) kúkú gbèrò eré ìfẹ́ sí i. Òun náà gbèrò rẹ̀,Tí kò bá jẹ́ pé ó rí ẹ̀rí Olúwa rẹ̀ (pé harāmu ni sìná, ìbá súnmọ́ ọn). Báyẹn ni (ọ̀rọ̀ náà rí) nítorí kí Á lè ṣẹ́rí aburú àti sìná ṣíṣe kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀. Dájúdájú ó wà nínú àwọn ẹrúsìn Wa, àwọn tí A ṣà lẹ́ṣà (fún ipò ànábì).”

Verse 25

وَٱسْتَبَقَا ٱلْبَابَ وَقَدَّتْ قَمِيصَهُۥ مِن دُبُرٍ وَأَلْفَيَا سَيِّدَهَا لَدَا ٱلْبَابِ ۚ قَالَتْ مَا جَزَآءُ مَنْ أَرَادَ بِأَهْلِكَ سُوٓءًا إِلَّآ أَن يُسْجَنَ أَوْ عَذَابٌ أَلِيمٌ

Transliteration wa-is'tabaqā l-bāba waqaddat qamīṣahu min duburin wa-alfayā sayyidahā ladā l-bābi qālat mā jazāu man arāda bi-ahlika sūan illā an yus'jana aw ʿadhābun alīmun

Yoruba Àwọn méjèèjì sáré lọ síbi ìlẹ̀kùn. (Obìnrin yìí) sì fa ẹ̀wù (Yūsuf) ya lẹ́yìn. Àwọn méjèèjì sì bá ọ̀gá rẹ̀ lẹ́nu ọ̀nà. (Obìnrin yìí) sì sọ pé: “Kí ni ẹ̀san fún ẹni tí ó gbèrò aburú sí ará ilé rẹ bí kò ṣe pé kí wọ́n sọ ọ́ sínú ọgbà ẹ̀wọ̀n tàbí ìyà ẹlẹ́ta-eléro.”

Verse 26

قَالَ هِىَ رَٰوَدَتْنِى عَن نَّفْسِى ۚ وَشَهِدَ شَاهِدٌ مِّنْ أَهْلِهَآ إِن كَانَ قَمِيصُهُۥ قُدَّ مِن قُبُلٍ فَصَدَقَتْ وَهُوَ مِنَ ٱلْكَـٰذِبِينَ

Transliteration qāla hiya rāwadatnī ʿan nafsī washahida shāhidun min ahlihā in kāna qamīṣuhu qudda min qubulin faṣadaqat wahuwa mina l-kādhibīna

Yoruba (Yūsuf) sọ pé: “Òun ló jírẹ̀ẹ́bẹ̀ fún eré ìfẹ́ lọ́dọ̀ mi.” Ẹlẹ́rìí kan nínú ará ile (obìnrin náà) sì jẹ́rìí pé: “Tí ó bá jẹ́ pé wọ́n fa ẹ̀wù rẹ̀ ya níwájú, (obìnrin yìí) ló sọ òdodo, (Yūsuf) sì wà nínú àwọn òpùrọ́.

Verse 27

وَإِن كَانَ قَمِيصُهُۥ قُدَّ مِن دُبُرٍ فَكَذَبَتْ وَهُوَ مِنَ ٱلصَّـٰدِقِينَ

Transliteration wa-in kāna qamīṣuhu qudda min duburin fakadhabat wahuwa mina l-ṣādiqīna

Yoruba Tí ó bá sì jẹ́ pé wọ́n fa ẹ̀wù rẹ̀ ya lẹ́yìn, (obìnrin yìí) ló parọ́, (Yūsuf) sì wà nínú àwọn olódodo.”1

Verse 28

فَلَمَّا رَءَا قَمِيصَهُۥ قُدَّ مِن دُبُرٍ قَالَ إِنَّهُۥ مِن كَيْدِكُنَّ ۖ إِنَّ كَيْدَكُنَّ عَظِيمٌ

Transliteration falammā raā qamīṣahu qudda min duburin qāla innahu min kaydikunna inna kaydakunna ʿaẓīmun

Yoruba Nígbà tí (ọkọ) rí ẹ̀wù rẹ̀ tí wọ́n ti fà á ya lẹ́yìn, ó sọ pé: “Dájúdájú nínú ète ẹ̀yin obìnrin ni (èyí). Dájúdájú ète yín tóbi.

Verse 29

يُوسُفُ أَعْرِضْ عَنْ هَـٰذَا ۚ وَٱسْتَغْفِرِى لِذَنۢبِكِ ۖ إِنَّكِ كُنتِ مِنَ ٱلْخَاطِـِٔينَ

Transliteration yūsufu aʿriḍ ʿan hādhā wa-is'taghfirī lidhanbiki innaki kunti mina l-khāṭiīna

Yoruba Yūsuf, ṣẹ́rí kúrò níbi èyí. Kí ìwọ (obìnrin yìí) sì tọrọ àforíjìn fún ẹ̀ṣẹ̀ rẹ. Dájúdájú ìwọ wà lára àwọn aláṣìṣe.”

Verse 30

۞ وَقَالَ نِسْوَةٌ فِى ٱلْمَدِينَةِ ٱمْرَأَتُ ٱلْعَزِيزِ تُرَٰوِدُ فَتَىٰهَا عَن نَّفْسِهِۦ ۖ قَدْ شَغَفَهَا حُبًّا ۖ إِنَّا لَنَرَىٰهَا فِى ضَلَـٰلٍ مُّبِينٍ

Transliteration waqāla nis'watun fī l-madīnati im'ra-atu l-ʿazīzi turāwidu fatāhā ʿan nafsihi qad shaghafahā ḥubban innā lanarāhā fī ḍalālin mubīnin

Yoruba Àwọn obìnrin kan nínú ìlú sọ pé: “Ayaba ń jírẹ̀ẹ́bẹ̀ fún eré ìfẹ́ lọ́dọ̀ ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀; ìfẹ́ kúkú ti kó sí i lọ́kàn. Dájúdájú àwa ń rí òun pé ó wà nínú àṣìṣe pọ́nńbélé.”

Verse 31

فَلَمَّا سَمِعَتْ بِمَكْرِهِنَّ أَرْسَلَتْ إِلَيْهِنَّ وَأَعْتَدَتْ لَهُنَّ مُتَّكَـًٔا وَءَاتَتْ كُلَّ وَٰحِدَةٍ مِّنْهُنَّ سِكِّينًا وَقَالَتِ ٱخْرُجْ عَلَيْهِنَّ ۖ فَلَمَّا رَأَيْنَهُۥٓ أَكْبَرْنَهُۥ وَقَطَّعْنَ أَيْدِيَهُنَّ وَقُلْنَ حَـٰشَ لِلَّهِ مَا هَـٰذَا بَشَرًا إِنْ هَـٰذَآ إِلَّا مَلَكٌ كَرِيمٌ

Transliteration falammā samiʿat bimakrihinna arsalat ilayhinna wa-aʿtadat lahunna muttaka-an waātat kulla wāḥidatin min'hunna sikkīnan waqālati ukh'ruj ʿalayhinna falammā ra-aynahu akbarnahu waqaṭṭaʿna aydiyahunna waqul'na ḥāsha lillahi mā hādhā basharan in hādhā illā malakun karīmun

Yoruba Nígbà tí (ayaba) gbọ́ ète (ọ̀rọ̀) wọn (tí wọ́n ń sọ nípa rẹ̀), ó ránṣẹ́ sí wọn. Ó sì pèsè ohun jíjẹ tí wọ́n máa rọ̀gbọ̀kú jẹ lórí tìmùtìmù àti ìrọ̀rí sílẹ̀ fún wọn. Ó fún ìkọ̀ọ̀kan wọn ní ọ̀bẹ (tí ó máa fi jẹun). Ó sì sọ pé: “Jáde sí wọn, (Yūsuf).” Nígbà tí wọ́n rí i, wọ́n gbé e tóbi (fún ẹwà ara rẹ̀). Wọ́n sì rẹ́ra wọn lọ́wọ́ (fún ìyanu ẹwà ara rẹ̀). Wọ́n sì wí pé: “Mímọ́ ni fún Allāhu! Èyí kì í ṣe abara. Kí ni èyí bí kò ṣe mọlāika alápọ̀n-ọ́nlé.”

Verse 32

قَالَتْ فَذَٰلِكُنَّ ٱلَّذِى لُمْتُنَّنِى فِيهِ ۖ وَلَقَدْ رَٰوَدتُّهُۥ عَن نَّفْسِهِۦ فَٱسْتَعْصَمَ ۖ وَلَئِن لَّمْ يَفْعَلْ مَآ ءَامُرُهُۥ لَيُسْجَنَنَّ وَلَيَكُونًا مِّنَ ٱلصَّـٰغِرِينَ

Transliteration qālat fadhālikunna alladhī lum'tunnanī fīhi walaqad rāwadttuhu ʿan nafsihi fa-is'taʿṣama wala-in lam yafʿal mā āmuruhu layus'jananna walayakūnan mina l-ṣāghirīna

Yoruba (Ayaba) sọ pé: “Ìyẹn ni ẹni tí ẹ bú mi fún. Dájúdájú mo jírẹ̀ẹ́bẹ̀ fún eré ìfẹ́ lọ́dọ̀ rẹ̀, ó sì wá ìṣọ́ra. Dájúdájú tí kò bá ṣe ohun tí mò ń pa láṣẹ fún un, wọ́n kúkú máa fi sínú ọgbà ẹ̀wọ̀n ni. Dájúdájú ó sì máa wà nínú àwọn ẹni yẹpẹrẹ.”

Verse 33

قَالَ رَبِّ ٱلسِّجْنُ أَحَبُّ إِلَىَّ مِمَّا يَدْعُونَنِىٓ إِلَيْهِ ۖ وَإِلَّا تَصْرِفْ عَنِّى كَيْدَهُنَّ أَصْبُ إِلَيْهِنَّ وَأَكُن مِّنَ ٱلْجَـٰهِلِينَ

Transliteration qāla rabbi l-sij'nu aḥabbu ilayya mimmā yadʿūnanī ilayhi wa-illā taṣrif ʿannī kaydahunna aṣbu ilayhinna wa-akun mina l-jāhilīna

Yoruba (Yūsuf) sọ pé: “Olúwa (Ẹlẹ́dàá) mi, ọgbà ẹ̀wọ̀n ni mo nífẹ̀ẹ́ sí ju ohun tí wọ́n ń pè mí sí. Tí O ò bá sì ṣẹ́rí ète wọn kúrò lọ́dọ̀ mi, èmi yóò kó sínú ète wọn, èmi yó sì wà lára àwọn aláìmọ̀kan.”

Verse 34

فَٱسْتَجَابَ لَهُۥ رَبُّهُۥ فَصَرَفَ عَنْهُ كَيْدَهُنَّ ۚ إِنَّهُۥ هُوَ ٱلسَّمِيعُ ٱلْعَلِيمُ

Transliteration fa-is'tajāba lahu rabbuhu faṣarafa ʿanhu kaydahunna innahu huwa l-samīʿu l-ʿalīmu

Yoruba Nítorí náà, Olúwa rẹ̀ jẹ́pè rẹ̀. Ó sì ṣẹ́rí ète wọn kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀. Dájúdájú Allāhu, Òun ni Olùgbọ́, Onímọ̀.

Verse 35

ثُمَّ بَدَا لَهُم مِّنۢ بَعْدِ مَا رَأَوُا۟ ٱلْـَٔايَـٰتِ لَيَسْجُنُنَّهُۥ حَتَّىٰ حِينٍ

Transliteration thumma badā lahum min baʿdi mā ra-awū l-āyāti layasjununnahu ḥattā ḥīnin

Yoruba Lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n ti rí àwọn àmì (pé Yūsuf kò jẹ̀bi ẹ̀sùn), lẹ́yìn náà, ó hàn sí wọn pé àwọn gbọ́dọ̀ sọ ọ́ sínú ọgbà ẹ̀wọ̀n títí di àsìkò kan ná.

Verse 36

وَدَخَلَ مَعَهُ ٱلسِّجْنَ فَتَيَانِ ۖ قَالَ أَحَدُهُمَآ إِنِّىٓ أَرَىٰنِىٓ أَعْصِرُ خَمْرًا ۖ وَقَالَ ٱلْـَٔاخَرُ إِنِّىٓ أَرَىٰنِىٓ أَحْمِلُ فَوْقَ رَأْسِى خُبْزًا تَأْكُلُ ٱلطَّيْرُ مِنْهُ ۖ نَبِّئْنَا بِتَأْوِيلِهِۦٓ ۖ إِنَّا نَرَىٰكَ مِنَ ٱلْمُحْسِنِينَ

Transliteration wadakhala maʿahu l-sij'na fatayāni qāla aḥaduhumā innī arānī aʿṣiru khamran waqāla l-ākharu innī arānī aḥmilu fawqa rasī khub'zan takulu l-ṭayru min'hu nabbi'nā bitawīlihi innā narāka mina l-muḥ'sinīna

Yoruba Àwọn ọ̀dọ́kùnrin méjì kan wọ inú ọgbà ẹ̀wọ̀n pẹ̀lú rẹ̀. Ọ̀kan nínú àwọn méjèèjì sọ pé: “Èmi lálàá rí ara mi pé mò ń fún ọtí.” Ẹnì kejì sọ pé: “Dájúdájú èmi lálàá rí ara mi pé mo gbé búrẹ́dì rù sórí mi, ẹyẹ sì ń jẹ nínú rẹ̀.” Sọ ìtúmọ̀ rẹ̀ fún wa. Dájúdájú àwa ń rí ọ pé o wà nínú àwọn ẹni rere.

Verse 37

قَالَ لَا يَأْتِيكُمَا طَعَامٌ تُرْزَقَانِهِۦٓ إِلَّا نَبَّأْتُكُمَا بِتَأْوِيلِهِۦ قَبْلَ أَن يَأْتِيَكُمَا ۚ ذَٰلِكُمَا مِمَّا عَلَّمَنِى رَبِّىٓ ۚ إِنِّى تَرَكْتُ مِلَّةَ قَوْمٍ لَّا يُؤْمِنُونَ بِٱللَّهِ وَهُم بِٱلْـَٔاخِرَةِ هُمْ كَـٰفِرُونَ

Transliteration qāla lā yatīkumā ṭaʿāmun tur'zaqānihi illā nabbatukumā bitawīlihi qabla an yatiyakumā dhālikumā mimmā ʿallamanī rabbī innī taraktu millata qawmin lā yu'minūna bil-lahi wahum bil-ākhirati hum kāfirūna

Yoruba Ó sọ pé: “Oúnjẹ tí wọ́n ń pèsè fún ẹ̀yin méjèèjì kò ní tí ì dé ba yín, àfi kí èmi ti sọ ìtúmọ̀ rẹ̀ fún ẹ̀yin méjèèjì ṣíwájú kí ó tó dé ba yín. Ìyẹn wà nínú n̄ǹkan tí Olúwa mi fi mọ̀ mí. Dájúdájú èmi fi ẹ̀sìn àwọn ènìyàn tí kò gbàgbọ́ nínú Allāhu sílẹ̀. Àwọn sì ni aláìgbàgbọ́ nínú Ọjọ́ Ìkẹ́yìn.

Verse 38

وَٱتَّبَعْتُ مِلَّةَ ءَابَآءِىٓ إِبْرَٰهِيمَ وَإِسْحَـٰقَ وَيَعْقُوبَ ۚ مَا كَانَ لَنَآ أَن نُّشْرِكَ بِٱللَّهِ مِن شَىْءٍ ۚ ذَٰلِكَ مِن فَضْلِ ٱللَّهِ عَلَيْنَا وَعَلَى ٱلنَّاسِ وَلَـٰكِنَّ أَكْثَرَ ٱلنَّاسِ لَا يَشْكُرُونَ

Transliteration wa-ittabaʿtu millata ābāī ib'rāhīma wa-is'ḥāqa wayaʿqūba mā kāna lanā an nush'rika bil-lahi min shayin dhālika min faḍli l-lahi ʿalaynā waʿalā l-nāsi walākinna akthara l-nāsi lā yashkurūna

Yoruba Mo sì tẹ̀lé ẹ̀sìn àwọn bàbá mi, (àwọn Ànábì) ’Ibrọ̄hīm, ’Ishāƙ àti Ya‘ƙūb. Kò tọ́ sí wa pé kí á sọ n̄ǹkan kan di akẹgbẹ́ fún Allāhu. Ìyẹn wà nínú oore àjùlọ Allāhu lórí àwa àti lórí àwọn ènìyàn, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ àwọn ènìyàn kì í dúpẹ́ (fún Allāhu).

Verse 39

يَـٰصَـٰحِبَىِ ٱلسِّجْنِ ءَأَرْبَابٌ مُّتَفَرِّقُونَ خَيْرٌ أَمِ ٱللَّهُ ٱلْوَٰحِدُ ٱلْقَهَّارُ

Transliteration yāṣāḥibayi l-sij'ni a-arbābun mutafarriqūna khayrun ami l-lahu l-wāḥidu l-qahāru

Yoruba Ẹ̀yin akẹgbẹ́ mi méjéèjì nínú ẹ̀wọ̀n, ṣé àwọn olúwa ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ló lóore jùlọ (láti jọ́sìn fún) tàbí Allāhu, Ọ̀kan ṣoṣo, Olùborí?

Verse 40

مَا تَعْبُدُونَ مِن دُونِهِۦٓ إِلَّآ أَسْمَآءً سَمَّيْتُمُوهَآ أَنتُمْ وَءَابَآؤُكُم مَّآ أَنزَلَ ٱللَّهُ بِهَا مِن سُلْطَـٰنٍ ۚ إِنِ ٱلْحُكْمُ إِلَّا لِلَّهِ ۚ أَمَرَ أَلَّا تَعْبُدُوٓا۟ إِلَّآ إِيَّاهُ ۚ ذَٰلِكَ ٱلدِّينُ ٱلْقَيِّمُ وَلَـٰكِنَّ أَكْثَرَ ٱلنَّاسِ لَا يَعْلَمُونَ

Transliteration mā taʿbudūna min dūnihi illā asmāan sammaytumūhā antum waābāukum mā anzala l-lahu bihā min sul'ṭānin ini l-ḥuk'mu illā lillahi amara allā taʿbudū illā iyyāhu dhālika l-dīnu l-qayimu walākinna akthara l-nāsi lā yaʿlamūna

Yoruba Kò sí ohun kan tí ẹ̀ ń jọ́sìn fún lẹ́yìn Rẹ̀ bí kò ṣe àwọn orúkọ kan tí ẹ sọ wọ́n - ẹ̀yin àti àwọn bàbá yín - Allāhu kò sọ ẹ̀rí kan kalẹ̀ fún un. Ìdájọ́ (ta ni a gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo) kò sí fún ẹnì kan àyàfi Allāhu. Ó sì ti pàṣẹ pé ẹ má ṣe jọ́sìn fún kiní kan àyàfi Òun nìkan. Ìyẹn ni ẹ̀sìn tó fẹsẹ̀ rinlẹ̀, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ àwọn ènìyàn kò mọ̀.

Verse 41

يَـٰصَـٰحِبَىِ ٱلسِّجْنِ أَمَّآ أَحَدُكُمَا فَيَسْقِى رَبَّهُۥ خَمْرًا ۖ وَأَمَّا ٱلْـَٔاخَرُ فَيُصْلَبُ فَتَأْكُلُ ٱلطَّيْرُ مِن رَّأْسِهِۦ ۚ قُضِىَ ٱلْأَمْرُ ٱلَّذِى فِيهِ تَسْتَفْتِيَانِ

Transliteration yāṣāḥibayi l-sij'ni ammā aḥadukumā fayasqī rabbahu khamran wa-ammā l-ākharu fayuṣ'labu fatakulu l-ṭayru min rasihi quḍiya l-amru alladhī fīhi tastaftiyāni

Yoruba Ẹ̀yin akẹgbẹ́ mi méjéèjì nínú ẹ̀wọ̀n, ní ti ẹnì kan nínú yín, ó máa fún ọ̀gá rẹ̀ ní ọtí mu. Ní ti ẹnì kejì, wọn yóò kàn án mọ́ igi, ẹyẹ yó sì máa jẹ nínú orí rẹ̀. Wọ́n ti parí ọ̀rọ̀ tí ẹ̀yin méjèèjì ń ṣe ìbéèrè nípa rẹ̀.”

Verse 42

وَقَالَ لِلَّذِى ظَنَّ أَنَّهُۥ نَاجٍ مِّنْهُمَا ٱذْكُرْنِى عِندَ رَبِّكَ فَأَنسَىٰهُ ٱلشَّيْطَـٰنُ ذِكْرَ رَبِّهِۦ فَلَبِثَ فِى ٱلسِّجْنِ بِضْعَ سِنِينَ

Transliteration waqāla lilladhī ẓanna annahu nājin min'humā udh'kur'nī ʿinda rabbika fa-ansāhu l-shayṭānu dhik'ra rabbihi falabitha fī l-sij'ni biḍ'ʿa sinīna

Yoruba Ó sì sọ fún ẹni tí ó rò pé ó máa là nínú àwọn méjèèjì pé: “Rántí mi lọ́dọ̀ ọ̀gá rẹ.” Èṣù sì mú (Yūsuf) gbàgbé ìrántí Olúwa rẹ̀ (nípa wíwá ìrànlọ́wọ́ sọ́dọ̀ ọ̀gá rẹ̀). Nítorí náà, ó wà nínú ọgbà ẹ̀wọ̀n fún àwọn ọdún díẹ̀.

Verse 43

وَقَالَ ٱلْمَلِكُ إِنِّىٓ أَرَىٰ سَبْعَ بَقَرَٰتٍ سِمَانٍ يَأْكُلُهُنَّ سَبْعٌ عِجَافٌ وَسَبْعَ سُنۢبُلَـٰتٍ خُضْرٍ وَأُخَرَ يَابِسَـٰتٍ ۖ يَـٰٓأَيُّهَا ٱلْمَلَأُ أَفْتُونِى فِى رُءْيَـٰىَ إِن كُنتُمْ لِلرُّءْيَا تَعْبُرُونَ

Transliteration waqāla l-maliku innī arā sabʿa baqarātin simānin yakuluhunna sabʿun ʿijāfun wasabʿa sunbulātin khuḍ'rin wa-ukhara yābisātin yāayyuhā l-mala-u aftūnī fī ru'yāya in kuntum lilrru'yā taʿburūna

Yoruba Ọbá sọ pé: “Dájúdájú èmi lálàá rí màálù méje tó sanra. Àwọn màálù méje tó rù sì ń jẹ wọ́n. (Mo tún lálàá rí) ṣiri méje tutù àti òmíràn gbígbẹ. Ẹ̀yin ìjòyè, ẹ fún mi ní àlàyé ìtúmọ̀ àlá mi tí ẹ bá jẹ́ ẹni tó máa ń túmọ̀ àlá.”

Verse 44

قَالُوٓا۟ أَضْغَـٰثُ أَحْلَـٰمٍ ۖ وَمَا نَحْنُ بِتَأْوِيلِ ٱلْأَحْلَـٰمِ بِعَـٰلِمِينَ

Transliteration qālū aḍghāthu aḥlāmin wamā naḥnu bitawīli l-aḥlāmi biʿālimīna

Yoruba Wọ́n sọ pé: “Àwọn àlá tí ó lọ́pọ̀ mọ́ra wọn tí kò ní ìtúmọ̀ (nìyí). Àti pé àwa kì í ṣe onímọ̀ nípa ìtúmọ̀ àwọn àlá.”

Verse 45

وَقَالَ ٱلَّذِى نَجَا مِنْهُمَا وَٱدَّكَرَ بَعْدَ أُمَّةٍ أَنَا۠ أُنَبِّئُكُم بِتَأْوِيلِهِۦ فَأَرْسِلُونِ

Transliteration waqāla alladhī najā min'humā wa-iddakara baʿda ummatin anā unabbi-ukum bitawīlihi fa-arsilūni

Yoruba Ẹni tí ó là nínú àwọn (ẹlẹ́wọ̀n) méjèèjì sọ pé, - ó rántí (Yūsuf) lẹ́yìn ìgbà pípẹ́ -: “Èmi yóò fún yín ní ìró nípa ìtúmọ̀ rẹ̀. Nítorí náà, ẹ fi iṣẹ́ rán mi ná (kí n̄g lọ ṣe ìwádìí rẹ̀).”

Verse 46

يُوسُفُ أَيُّهَا ٱلصِّدِّيقُ أَفْتِنَا فِى سَبْعِ بَقَرَٰتٍ سِمَانٍ يَأْكُلُهُنَّ سَبْعٌ عِجَافٌ وَسَبْعِ سُنۢبُلَـٰتٍ خُضْرٍ وَأُخَرَ يَابِسَـٰتٍ لَّعَلِّىٓ أَرْجِعُ إِلَى ٱلنَّاسِ لَعَلَّهُمْ يَعْلَمُونَ

Transliteration yūsufu ayyuhā l-ṣidīqu aftinā fī sabʿi baqarātin simānin yakuluhunna sabʿun ʿijāfun wasabʿi sunbulātin khuḍ'rin wa-ukhara yābisātin laʿallī arjiʿu ilā l-nāsi laʿallahum yaʿlamūna

Yoruba Yūsuf, ìwọ olódodo, fún wa ní àlàyé ìtúmọ̀ àlá (yìí): màálù méje tó sanra. Àwọn màálù méje tó rù sì ń jẹ wọ́n. Àti ṣiri méje tutù àti òmíràn gbígbẹ. (Kí ni ìtúmọ̀ rẹ̀) nítorí kí n̄g lè fi àbọ̀ sọ́dọ̀ àwọn ènìyàn àti nítorí kí wọ́n lè mọ (ìtúmọ̀ rẹ̀).

Verse 47

قَالَ تَزْرَعُونَ سَبْعَ سِنِينَ دَأَبًا فَمَا حَصَدتُّمْ فَذَرُوهُ فِى سُنۢبُلِهِۦٓ إِلَّا قَلِيلًا مِّمَّا تَأْكُلُونَ

Transliteration qāla tazraʿūna sabʿa sinīna da-aban famā ḥaṣadttum fadharūhu fī sunbulihi illā qalīlan mimmā takulūna

Yoruba Ó sọ pé: “Ẹ̀yin yóò gbin n̄ǹkan ọ̀gbìn fún ọdún méje gbáko (gẹ́gẹ́ bí) ìṣe (yín). Ohunkòhun tí ẹ bá kó lérè oko, kí ẹ fi sílẹ̀ sínú ṣiri rẹ̀ àfi díẹ̀ tí ẹ máa jẹ nínú rẹ̀.

Verse 48

ثُمَّ يَأْتِى مِنۢ بَعْدِ ذَٰلِكَ سَبْعٌ شِدَادٌ يَأْكُلْنَ مَا قَدَّمْتُمْ لَهُنَّ إِلَّا قَلِيلًا مِّمَّا تُحْصِنُونَ

Transliteration thumma yatī min baʿdi dhālika sabʿun shidādun yakul'na mā qaddamtum lahunna illā qalīlan mimmā tuḥ'ṣinūna

Yoruba Lẹ́yìn náà, ọdún méje tó le (fún ọ̀dá òjò) yóò dé lẹ́yìn ìyẹn, (àwọn ará ìlú) yó sì lè jẹ ohun tí ẹ ti (kó lérè oko) ṣíwájú àfi díẹ̀ tí ẹ máa fi pamọ́ (fún gbígbìn).

Verse 49

ثُمَّ يَأْتِى مِنۢ بَعْدِ ذَٰلِكَ عَامٌ فِيهِ يُغَاثُ ٱلنَّاسُ وَفِيهِ يَعْصِرُونَ

Transliteration thumma yatī min baʿdi dhālika ʿāmun fīhi yughāthu l-nāsu wafīhi yaʿṣirūna

Yoruba Lẹ́yìn náà, ọdún kan tí Wọn yóò rọ̀jò fún àwọn ènìyàn yóò dé lẹ́yìn ìyẹn. Àwọn ènìyàn yó sì máa fún èso àti wàrà mu nínú ọdún náà.

Verse 50

وَقَالَ ٱلْمَلِكُ ٱئْتُونِى بِهِۦ ۖ فَلَمَّا جَآءَهُ ٱلرَّسُولُ قَالَ ٱرْجِعْ إِلَىٰ رَبِّكَ فَسْـَٔلْهُ مَا بَالُ ٱلنِّسْوَةِ ٱلَّـٰتِى قَطَّعْنَ أَيْدِيَهُنَّ ۚ إِنَّ رَبِّى بِكَيْدِهِنَّ عَلِيمٌ

Transliteration waqāla l-maliku i'tūnī bihi falammā jāahu l-rasūlu qāla ir'jiʿ ilā rabbika fasalhu mā bālu l-nis'wati allātī qaṭṭaʿna aydiyahunna inna rabbī bikaydihinna ʿalīmun

Yoruba Ọba sọ pé: “Ẹ mú (Yūsuf) wá fún mi.” Nígbà tí ìránṣẹ́ náà dé ọ̀dọ̀ rẹ. (Yūsuf) sọ pé: “Padà sọ́dọ̀ ọ̀gá rẹ, kí o bi í léèrè pé, kí ni ó ṣẹlẹ̀ sí àwọn obìnrin tí wọ́n rẹ́ ọwọ́ ara wọn. Dájúdájú Olúwa mi ni Onímọ̀ nípa ète wọn.”

Verse 51

قَالَ مَا خَطْبُكُنَّ إِذْ رَٰوَدتُّنَّ يُوسُفَ عَن نَّفْسِهِۦ ۚ قُلْنَ حَـٰشَ لِلَّهِ مَا عَلِمْنَا عَلَيْهِ مِن سُوٓءٍ ۚ قَالَتِ ٱمْرَأَتُ ٱلْعَزِيزِ ٱلْـَٔـٰنَ حَصْحَصَ ٱلْحَقُّ أَنَا۠ رَٰوَدتُّهُۥ عَن نَّفْسِهِۦ وَإِنَّهُۥ لَمِنَ ٱلصَّـٰدِقِينَ

Transliteration qāla mā khaṭbukunna idh rāwadttunna yūsufa ʿan nafsihi qul'na ḥāsha lillahi mā ʿalim'nā ʿalayhi min sūin qālati im'ra-atu l-ʿazīzi l-āna ḥaṣḥaṣa l-ḥaqu anā rāwadttuhu ʿan nafsihi wa-innahu lamina l-ṣādiqīna

Yoruba (Ọba) sọ pé: “Kí ni ọ̀rọ̀ tiyín ti jẹ́ tí ẹ fi jírẹ̀ẹ́bẹ̀ fún eré ìfẹ́ lọ́dọ̀ Yūsuf?” Wọ́n sọ pé: “Mímọ́ ni fún Allāhu. àwa kò mọ aburú kan mọ Yūsuf.” Ayaba sọ pé: “Nísinsìn yìí ni òdodo fojú hàn. Èmi ni mo jírẹ̀ẹ́bẹ̀ fún eré ìfẹ́ lọ́dọ̀ rẹ̀. Dájúdájú ó wà nínú àwọn olódodo.”

Verse 52

ذَٰلِكَ لِيَعْلَمَ أَنِّى لَمْ أَخُنْهُ بِٱلْغَيْبِ وَأَنَّ ٱللَّهَ لَا يَهْدِى كَيْدَ ٱلْخَآئِنِينَ

Transliteration dhālika liyaʿlama annī lam akhun'hu bil-ghaybi wa-anna l-laha lā yahdī kayda l-khāinīna

Yoruba (Yūsuf sọ pé): “Ìyẹn nítorí kí ọba lè mọ̀ pé dájúdájú èmi kò jàǹbá rẹ̀ ní ìkọ̀kọ̀. Àti pé dájúdájú Allāhu kò níí fi ìmọ̀nà síbi ète àwọn oníjàǹbá.

Verse 53

۞ وَمَآ أُبَرِّئُ نَفْسِىٓ ۚ إِنَّ ٱلنَّفْسَ لَأَمَّارَةٌۢ بِٱلسُّوٓءِ إِلَّا مَا رَحِمَ رَبِّىٓ ۚ إِنَّ رَبِّى غَفُورٌ رَّحِيمٌ

Transliteration wamā ubarri-u nafsī inna l-nafsa la-ammāratun bil-sūi illā mā raḥima rabbī inna rabbī ghafūrun raḥīmun

Yoruba Èmi kò sì fọra mi mọ́ (níbi èròkérò); dájúdájú ẹ̀mí kúkú ń pàṣẹ èròkérò (fún ẹ̀dá) ni àfi ẹni tí Olúwa mi bá kẹ́. Dájúdájú Olúwa mi ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.”

Verse 54

وَقَالَ ٱلْمَلِكُ ٱئْتُونِى بِهِۦٓ أَسْتَخْلِصْهُ لِنَفْسِى ۖ فَلَمَّا كَلَّمَهُۥ قَالَ إِنَّكَ ٱلْيَوْمَ لَدَيْنَا مَكِينٌ أَمِينٌ

Transliteration waqāla l-maliku i'tūnī bihi astakhliṣ'hu linafsī falammā kallamahu qāla innaka l-yawma ladaynā makīnun amīnun

Yoruba Ọba sọ pé: “Ẹ mú (Yūsuf) wá fún mi. Èmi yóò ṣe é ní ẹni ẹ̀ṣà lọ́dọ̀ mi.” Nígbà tí ọba bá a sọ̀rọ̀ tán, ó sọ pé: “Lọ́dọ̀ wa ní òní dájúdájú ìwọ ni ẹni pàtàkì, olùfọkàntán.”

Verse 55

قَالَ ٱجْعَلْنِى عَلَىٰ خَزَآئِنِ ٱلْأَرْضِ ۖ إِنِّى حَفِيظٌ عَلِيمٌ

Transliteration qāla ij'ʿalnī ʿalā khazāini l-arḍi innī ḥafīẓun ʿalīmun

Yoruba (Yūsuf) sọ pé: “Fi mí ṣe aláṣẹ lórí àwọn ọrọ̀ ìlú, dájúdájú alámòjúútó onímọ̀ ni mí.”

Verse 56

وَكَذَٰلِكَ مَكَّنَّا لِيُوسُفَ فِى ٱلْأَرْضِ يَتَبَوَّأُ مِنْهَا حَيْثُ يَشَآءُ ۚ نُصِيبُ بِرَحْمَتِنَا مَن نَّشَآءُ ۖ وَلَا نُضِيعُ أَجْرَ ٱلْمُحْسِنِينَ

Transliteration wakadhālika makkannā liyūsufa fī l-arḍi yatabawwa-u min'hā ḥaythu yashāu nuṣību biraḥmatinā man nashāu walā nuḍīʿu ajra l-muḥ'sinīna

Yoruba Báyẹn ni A ṣe fún Yūsuf ní ipò àti ibùgbé lórí ilẹ̀. Ó sì ń gbé ní ibi tí ó bá fẹ́. Àwa ń mú ìkẹ́ Wa bá ẹnikẹ́ni tí A bá fẹ́. A ò sì níí fi ẹ̀san àwọn olùṣe-rere ráre.

Verse 57

وَلَأَجْرُ ٱلْـَٔاخِرَةِ خَيْرٌ لِّلَّذِينَ ءَامَنُوا۟ وَكَانُوا۟ يَتَّقُونَ

Transliteration wala-ajru l-ākhirati khayrun lilladhīna āmanū wakānū yattaqūna

Yoruba Dájúdájú ẹ̀san ti ọ̀run lóore jùlọ fún àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ń bẹ̀rù (Allāhu).

Verse 58

وَجَآءَ إِخْوَةُ يُوسُفَ فَدَخَلُوا۟ عَلَيْهِ فَعَرَفَهُمْ وَهُمْ لَهُۥ مُنكِرُونَ

Transliteration wajāa ikh'watu yūsufa fadakhalū ʿalayhi faʿarafahum wahum lahu munkirūna

Yoruba Àwọn ọbàkan (Ànábì) Yūsuf dé, wọ́n sì wọlé tọ̀ ọ́. Ó dá wọn mọ̀. Àwọn kò sì mọ̀ ọ́n mọ́.

Verse 59

وَلَمَّا جَهَّزَهُم بِجَهَازِهِمْ قَالَ ٱئْتُونِى بِأَخٍ لَّكُم مِّنْ أَبِيكُمْ ۚ أَلَا تَرَوْنَ أَنِّىٓ أُوفِى ٱلْكَيْلَ وَأَنَا۠ خَيْرُ ٱلْمُنزِلِينَ

Transliteration walammā jahhazahum bijahāzihim qāla i'tūnī bi-akhin lakum min abīkum alā tarawna annī ūfī l-kayla wa-anā khayru l-munzilīna

Yoruba Nígbà tí ó sì fún wọn ní ẹrù oúnjẹ wọn tán, ó sọ pé: “Ẹ lọ mú ọbàkan yín wá láti ọ̀dọ̀ bàbá yín. Ṣé ẹ kò rí i pé dájúdájú mò ń wọn kóńgò ní ẹ̀kún rẹ́rẹ́ ni? Èmi sì dára jùlọ nínú àwọn olùgbàlejò.

Verse 60

فَإِن لَّمْ تَأْتُونِى بِهِۦ فَلَا كَيْلَ لَكُمْ عِندِى وَلَا تَقْرَبُونِ

Transliteration fa-in lam tatūnī bihi falā kayla lakum ʿindī walā taqrabūni

Yoruba Tí ẹ ò bá sì mú un wá, kò sí (ẹrù oúnjẹ) wíwọ̀n fún yín lọ́dọ̀ mi. Kí ẹ sì má ṣe súnmọ́ mi.”

Verse 61

قَالُوا۟ سَنُرَٰوِدُ عَنْهُ أَبَاهُ وَإِنَّا لَفَـٰعِلُونَ

Transliteration qālū sanurāwidu ʿanhu abāhu wa-innā lafāʿilūna

Yoruba Wọ́n sọ pé: “A máa jírẹ̀ẹ́bẹ̀ fún un lọ́dọ̀ bàbá rẹ̀. Dájúdájú àwa máa ṣe bẹ́ẹ̀.”

Verse 62

وَقَالَ لِفِتْيَـٰنِهِ ٱجْعَلُوا۟ بِضَـٰعَتَهُمْ فِى رِحَالِهِمْ لَعَلَّهُمْ يَعْرِفُونَهَآ إِذَا ٱنقَلَبُوٓا۟ إِلَىٰٓ أَهْلِهِمْ لَعَلَّهُمْ يَرْجِعُونَ

Transliteration waqāla lifit'yānihi ij'ʿalū biḍāʿatahum fī riḥālihim laʿallahum yaʿrifūnahā idhā inqalabū ilā ahlihim laʿallahum yarjiʿūna

Yoruba Ó sì sọ fún àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ pé: “Ẹ fi owó-ọjà wọn sínú ẹrù (oúnjẹ) wọn nítorí kí wọ́n lè mọ̀ nígbà tí wọ́n bá padà dé ọ̀dọ̀ ará ilé wọ́n (pé a ti dá a padà fún wọn), wọn yó sì lè padà wá.”

Verse 63

فَلَمَّا رَجَعُوٓا۟ إِلَىٰٓ أَبِيهِمْ قَالُوا۟ يَـٰٓأَبَانَا مُنِعَ مِنَّا ٱلْكَيْلُ فَأَرْسِلْ مَعَنَآ أَخَانَا نَكْتَلْ وَإِنَّا لَهُۥ لَحَـٰفِظُونَ

Transliteration falammā rajaʿū ilā abīhim qālū yāabānā muniʿa minnā l-kaylu fa-arsil maʿanā akhānā naktal wa-innā lahu laḥāfiẓūna

Yoruba Nígbà tí wọ́n padà dé ọ̀dọ̀ bàbá wọn, wọ́n sọ pé: “Bàbá wa, wọ́n kọ̀ láti wọn oúnjẹ fún wa. Nítorí náà, jẹ́ kí ọbàkan wa bá wa lọ nítorí kí á lè rí oúnjẹ wọ̀n (wálé). Dájúdájú àwa yóò máa ṣọ́ ọ.”

Verse 64

قَالَ هَلْ ءَامَنُكُمْ عَلَيْهِ إِلَّا كَمَآ أَمِنتُكُمْ عَلَىٰٓ أَخِيهِ مِن قَبْلُ ۖ فَٱللَّهُ خَيْرٌ حَـٰفِظًا ۖ وَهُوَ أَرْحَمُ ٱلرَّٰحِمِينَ

Transliteration qāla hal āmanukum ʿalayhi illā kamā amintukum ʿalā akhīhi min qablu fal-lahu khayrun ḥāfiẓan wahuwa arḥamu l-rāḥimīna

Yoruba Ó sọ pé: “Ṣé kí n̄g gbà yín gbọ́ lórí rẹ̀ bí kò ṣe bí mó ṣe gbà yín gbọ́ ní ìṣaájú lórí ọmọ-ìyá rẹ̀? Nítorí náà, Allāhu lóore jùlọ ní Olùṣọ́. Òun sì ni Aláàánú-jùlọ nínú àwọn aláàánú.”

Verse 65

وَلَمَّا فَتَحُوا۟ مَتَـٰعَهُمْ وَجَدُوا۟ بِضَـٰعَتَهُمْ رُدَّتْ إِلَيْهِمْ ۖ قَالُوا۟ يَـٰٓأَبَانَا مَا نَبْغِى ۖ هَـٰذِهِۦ بِضَـٰعَتُنَا رُدَّتْ إِلَيْنَا ۖ وَنَمِيرُ أَهْلَنَا وَنَحْفَظُ أَخَانَا وَنَزْدَادُ كَيْلَ بَعِيرٍ ۖ ذَٰلِكَ كَيْلٌ يَسِيرٌ

Transliteration walammā fataḥū matāʿahum wajadū biḍāʿatahum ruddat ilayhim qālū yāabānā mā nabghī hādhihi biḍāʿatunā ruddat ilaynā wanamīru ahlanā wanaḥfaẓu akhānā wanazdādu kayla baʿīrin dhālika kaylun yasīrun

Yoruba Nígbà tí wọ́n tú ẹrù oúnjẹ wọn, wọ́n rí owó-ọjà wọn tí wọ́n dá padà fún wọn (nínú rẹ̀). Wọ́n sọ pé: “Bàbá wa, kí ni a tún ń fẹ́? Owó-ọjà wa nìyí tí wọ́n ti dá padà fún wa. A ó si tún fi wá oúnjẹ rà fún àwọn ẹbí wa. A ó sì dáàbò bo ọbàkan wa. A sì máa rí àlékún ẹrù oúnjẹ (tí) ràkúnmí kan lè rù sí i. Ìwọ̀n oúnjẹ kékeré sì nìyẹn (lọ́dọ̀ ọba).”

Verse 66

قَالَ لَنْ أُرْسِلَهُۥ مَعَكُمْ حَتَّىٰ تُؤْتُونِ مَوْثِقًا مِّنَ ٱللَّهِ لَتَأْتُنَّنِى بِهِۦٓ إِلَّآ أَن يُحَاطَ بِكُمْ ۖ فَلَمَّآ ءَاتَوْهُ مَوْثِقَهُمْ قَالَ ٱللَّهُ عَلَىٰ مَا نَقُولُ وَكِيلٌ

Transliteration qāla lan ur'silahu maʿakum ḥattā tu'tūni mawthiqan mina l-lahi latatunnanī bihi illā an yuḥāṭa bikum falammā ātawhu mawthiqahum qāla l-lahu ʿalā mā naqūlu wakīlun

Yoruba Ó sọ pé: “Èmi kò níí jẹ́ kí ó ba yín lọ títí ẹ máa fi ṣe àdéhùn fún mi ní (orúkọ) Allāhu pé dájúdájú ẹ máa mú un padà wá bá mi àfi tí (àwọn ọ̀tá) bá ka yín mọ́.” Nígbà tí wọ́n fún un ní àdéhùn wọn tán, ó sọ pé: “Allāhu ni Ẹlẹ́rìí lórí ohun tí à ń sọ (yìí).”

Verse 67

وَقَالَ يَـٰبَنِىَّ لَا تَدْخُلُوا۟ مِنۢ بَابٍ وَٰحِدٍ وَٱدْخُلُوا۟ مِنْ أَبْوَٰبٍ مُّتَفَرِّقَةٍ ۖ وَمَآ أُغْنِى عَنكُم مِّنَ ٱللَّهِ مِن شَىْءٍ ۖ إِنِ ٱلْحُكْمُ إِلَّا لِلَّهِ ۖ عَلَيْهِ تَوَكَّلْتُ ۖ وَعَلَيْهِ فَلْيَتَوَكَّلِ ٱلْمُتَوَكِّلُونَ

Transliteration waqāla yābaniyya lā tadkhulū min bābin wāḥidin wa-ud'khulū min abwābin mutafarriqatin wamā ugh'nī ʿankum mina l-lahi min shayin ini l-ḥuk'mu illā lillahi ʿalayhi tawakkaltu waʿalayhi falyatawakkali l-mutawakilūna

Yoruba Ó tún sọ pé: “Ẹ̀yin ọmọ mi, ẹ má ṣe gba ẹnu ọ̀nà ẹyọ kan wọlé. Ẹ gba ẹnu ọ̀nà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ wọlé. Èmi kò lè fí n̄ǹkan kan rọ̀ yín lọ́rọ̀ lọ́dọ̀ Allāhu. Kò sí ìdájọ́ (kan) àfi ti Allāhu. Òun ni mo gbáralé. Òun sì ni kí àwọn olùgbáralé gbáralé.”

Verse 68

وَلَمَّا دَخَلُوا۟ مِنْ حَيْثُ أَمَرَهُمْ أَبُوهُم مَّا كَانَ يُغْنِى عَنْهُم مِّنَ ٱللَّهِ مِن شَىْءٍ إِلَّا حَاجَةً فِى نَفْسِ يَعْقُوبَ قَضَىٰهَا ۚ وَإِنَّهُۥ لَذُو عِلْمٍ لِّمَا عَلَّمْنَـٰهُ وَلَـٰكِنَّ أَكْثَرَ ٱلنَّاسِ لَا يَعْلَمُونَ

Transliteration walammā dakhalū min ḥaythu amarahum abūhum mā kāna yugh'nī ʿanhum mina l-lahi min shayin illā ḥājatan fī nafsi yaʿqūba qaḍāhā wa-innahu ladhū ʿil'min limā ʿallamnāhu walākinna akthara l-nāsi lā yaʿlamūna

Yoruba Nígbà tí wọ́n wọ (inú ìlú) ní àwọn àyè tí bàbá wọn pa láṣẹ fún wọn, kò sì rọ̀ wọ́n lọ́rọ̀ kan kan lọ́dọ̀ Allāhu bí kò ṣe bùkátà kan nínú ẹ̀mí (Ànábì) Ya‘ƙūb tí ó múṣẹ. Dájúdájú onímọ̀ ni nípa ohun tí A fi mọ̀ ọ́n, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ àwọn ènìyàn kò mọ̀.

Verse 69

وَلَمَّا دَخَلُوا۟ عَلَىٰ يُوسُفَ ءَاوَىٰٓ إِلَيْهِ أَخَاهُ ۖ قَالَ إِنِّىٓ أَنَا۠ أَخُوكَ فَلَا تَبْتَئِسْ بِمَا كَانُوا۟ يَعْمَلُونَ

Transliteration walammā dakhalū ʿalā yūsufa āwā ilayhi akhāhu qāla innī anā akhūka falā tabta-is bimā kānū yaʿmalūna

Yoruba Nígbà tí wọ́n wọlé ti (Ànábì) Yūsuf, ó mú ọmọ-ìyá rẹ̀ mọ́ra sọ́dọ̀ rẹ̀. Ó sọ pé: “Dájúdájú èmi ni ọmọ-ìyá rẹ. Nítorí náà, má ṣe banújẹ́ nípa ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́.”

Verse 70

فَلَمَّا جَهَّزَهُم بِجَهَازِهِمْ جَعَلَ ٱلسِّقَايَةَ فِى رَحْلِ أَخِيهِ ثُمَّ أَذَّنَ مُؤَذِّنٌ أَيَّتُهَا ٱلْعِيرُ إِنَّكُمْ لَسَـٰرِقُونَ

Transliteration falammā jahhazahum bijahāzihim jaʿala l-siqāyata fī raḥli akhīhi thumma adhana mu-adhinun ayyatuhā l-ʿīru innakum lasāriqūna

Yoruba Nígbà tí ó sì fún wọn ní ẹrù wọn tán, ó fi ife-ìmumi sínú ẹrù ọmọ-ìyá rẹ̀. Lẹ́yìn náà, olùpèpè kan kéde pé: “Ẹ̀yin èrò-ràkúnmí, dájúdájú olè mà ni yín.”

Verse 71

قَالُوا۟ وَأَقْبَلُوا۟ عَلَيْهِم مَّاذَا تَفْقِدُونَ

Transliteration qālū wa-aqbalū ʿalayhim mādhā tafqidūna

Yoruba Wọ́n dojú kọ wọ́n, wọ́n sọ pé: “Kí l’ẹ ṣàfẹ́kù?”

Verse 72

قَالُوا۟ نَفْقِدُ صُوَاعَ ٱلْمَلِكِ وَلِمَن جَآءَ بِهِۦ حِمْلُ بَعِيرٍ وَأَنَا۠ بِهِۦ زَعِيمٌ

Transliteration qālū nafqidu ṣuwāʿa l-maliki waliman jāa bihi ḥim'lu baʿīrin wa-anā bihi zaʿīmun

Yoruba Wọ́n sọ pé: “A ṣàfẹ́kù ife ọba ni. Ẹni tí ó bá sì mú un wá yóò rí ẹrù oúnjẹ ràkúnmí kan gbà. Èmi sì ni onídùróó fún ẹ̀bùn náà.”

Verse 73

قَالُوا۟ تَٱللَّهِ لَقَدْ عَلِمْتُم مَّا جِئْنَا لِنُفْسِدَ فِى ٱلْأَرْضِ وَمَا كُنَّا سَـٰرِقِينَ

Transliteration qālū tal-lahi laqad ʿalim'tum mā ji'nā linuf'sida fī l-arḍi wamā kunnā sāriqīna

Yoruba Wọ́n sọ pé: “A fi Allāhu búra, dájúdájú ẹ mọ̀ pé a kò wá láti ṣèbàjẹ́ lórí ilẹ̀. Àti pé àwa kì í ṣe olè.”

Verse 74

قَالُوا۟ فَمَا جَزَٰٓؤُهُۥٓ إِن كُنتُمْ كَـٰذِبِينَ

Transliteration qālū famā jazāuhu in kuntum kādhibīna

Yoruba Wọ́n sọ pé: “Kí ni ẹ̀san (fún ẹni tí) ó jí i, tí (ó bá hàn pé) ẹ̀yin jẹ́ òpùrọ́?”

Verse 75

قَالُوا۟ جَزَٰٓؤُهُۥ مَن وُجِدَ فِى رَحْلِهِۦ فَهُوَ جَزَٰٓؤُهُۥ ۚ كَذَٰلِكَ نَجْزِى ٱلظَّـٰلِمِينَ

Transliteration qālū jazāuhu man wujida fī raḥlihi fahuwa jazāuhu kadhālika najzī l-ẓālimīna

Yoruba Wọ́n sọ pé: “Ẹ̀san rẹ̀; ẹni tí wọ́n bá bá a nínú ẹrù rẹ̀, òun náà ni ẹ̀san rẹ̀. Báyẹn ni àwa ṣe ń san àwọn alábòsí ní ẹ̀san (ní ọ̀dọ̀ tiwa).”1

Verse 76

فَبَدَأَ بِأَوْعِيَتِهِمْ قَبْلَ وِعَآءِ أَخِيهِ ثُمَّ ٱسْتَخْرَجَهَا مِن وِعَآءِ أَخِيهِ ۚ كَذَٰلِكَ كِدْنَا لِيُوسُفَ ۖ مَا كَانَ لِيَأْخُذَ أَخَاهُ فِى دِينِ ٱلْمَلِكِ إِلَّآ أَن يَشَآءَ ٱللَّهُ ۚ نَرْفَعُ دَرَجَـٰتٍ مَّن نَّشَآءُ ۗ وَفَوْقَ كُلِّ ذِى عِلْمٍ عَلِيمٌ

Transliteration fabada-a bi-awʿiyatihim qabla wiʿāi akhīhi thumma is'takhrajahā min wiʿāi akhīhi kadhālika kid'nā liyūsufa mā kāna liyakhudha akhāhu fī dīni l-maliki illā an yashāa l-lahu narfaʿu darajātin man nashāu wafawqa kulli dhī ʿil'min ʿalīmun

Yoruba Ó sì bẹ̀rẹ̀ (àyẹ̀wò) pẹ̀lú àpò wọn ṣíwájú àpò ọmọ-ìyá rẹ̀. Lẹ́yìn náà, ó mú un jáde láti inú àpò ọmọ-ìyá rẹ̀. Báyẹn ní A ṣe fún (Ànábì) Yūsuf ní ète dá. Kò lè fi òfin ọba mú ọmọ-ìyá rẹ̀ àfi tí Allāhu bá fẹ́.À ń ṣàgbéga àwọn ipò fún ẹni tí A bá fẹ́. Onímọ̀ wà lókè gbogbo onímọ̀.2

Verse 77

۞ قَالُوٓا۟ إِن يَسْرِقْ فَقَدْ سَرَقَ أَخٌ لَّهُۥ مِن قَبْلُ ۚ فَأَسَرَّهَا يُوسُفُ فِى نَفْسِهِۦ وَلَمْ يُبْدِهَا لَهُمْ ۚ قَالَ أَنتُمْ شَرٌّ مَّكَانًا ۖ وَٱللَّهُ أَعْلَمُ بِمَا تَصِفُونَ

Transliteration qālū in yasriq faqad saraqa akhun lahu min qablu fa-asarrahā yūsufu fī nafsihi walam yub'dihā lahum qāla antum sharrun makānan wal-lahu aʿlamu bimā taṣifūna

Yoruba Wọ́n sọ pé: “Tí ó bá jalè, dájúdájú ọmọ-ìyá rẹ̀ kan ti jalè ṣíwájú.” (Ànábì) Yūsuf sì fi ọ̀rọ̀ náà pamọ́ sínú ẹ̀mí rẹ̀, kò sì fi hàn sí wọn pé (kò rí bẹ́ẹ̀). Ó (sì) sọ pé: “Ẹ̀yin lẹ burú jùlọ ní ipò. Allāhu l’Ó sì nímọ̀ jùlọ nípa ohun tí ẹ̀ ń ròyìn rẹ̀.”

Verse 78

قَالُوا۟ يَـٰٓأَيُّهَا ٱلْعَزِيزُ إِنَّ لَهُۥٓ أَبًا شَيْخًا كَبِيرًا فَخُذْ أَحَدَنَا مَكَانَهُۥٓ ۖ إِنَّا نَرَىٰكَ مِنَ ٱلْمُحْسِنِينَ

Transliteration qālū yāayyuhā l-ʿazīzu inna lahu aban shaykhan kabīran fakhudh aḥadanā makānahu innā narāka mina l-muḥ'sinīna

Yoruba Wọ́n sọ pé: “Ìwọ ọba, dájúdájú ó ní bàbá arúgbó àgbàlágbà kan. Nítorí náà, mú ẹnì kan nínú wa dípò rẹ̀. Dájúdájú àwa ń rí ìwọ pé o wà nínú àwọn ẹni-rere.”

Verse 79

قَالَ مَعَاذَ ٱللَّهِ أَن نَّأْخُذَ إِلَّا مَن وَجَدْنَا مَتَـٰعَنَا عِندَهُۥٓ إِنَّآ إِذًا لَّظَـٰلِمُونَ

Transliteration qāla maʿādha l-lahi an nakhudha illā man wajadnā matāʿanā ʿindahu innā idhan laẓālimūna

Yoruba Ó sọ pé: “Mo sádi Allāhu pé kí á mú ẹnì kan àfi ẹni tí a bá ẹrù wa lọ́dọ̀ rẹ. (Tí a bá mú ẹlòmíìràn) dájúdájú nígbà náà alábòsí ni wá.”

Verse 80

فَلَمَّا ٱسْتَيْـَٔسُوا۟ مِنْهُ خَلَصُوا۟ نَجِيًّا ۖ قَالَ كَبِيرُهُمْ أَلَمْ تَعْلَمُوٓا۟ أَنَّ أَبَاكُمْ قَدْ أَخَذَ عَلَيْكُم مَّوْثِقًا مِّنَ ٱللَّهِ وَمِن قَبْلُ مَا فَرَّطتُمْ فِى يُوسُفَ ۖ فَلَنْ أَبْرَحَ ٱلْأَرْضَ حَتَّىٰ يَأْذَنَ لِىٓ أَبِىٓ أَوْ يَحْكُمَ ٱللَّهُ لِى ۖ وَهُوَ خَيْرُ ٱلْحَـٰكِمِينَ

Transliteration falammā is'tayasū min'hu khalaṣū najiyyan qāla kabīruhum alam taʿlamū anna abākum qad akhadha ʿalaykum mawthiqan mina l-lahi wamin qablu mā farraṭtum fī yūsufa falan abraḥa l-arḍa ḥattā yadhana lī abī aw yaḥkuma l-lahu lī wahuwa khayru l-ḥākimīna

Yoruba Nígbà tí wọ́n sọ̀rètí nù lórí ọ̀rọ̀ rẹ̀, wọ́n tẹ̀ sọ̀rọ̀. Àgbà (nínú) wọn sọ pé: “Ṣé ẹ kò mọ̀ pé dájúdájú bàbá yín ti gba àdéhùn yín tí (ẹ ṣe ní orúkọ) Allāhu. Àti pé ṣíwájú (èyí, ohun tí ẹ ṣe ní) àṣeètó lórí ọ̀rọ̀ (Ànábì) Yūsuf. Nítorí náà, èmi kò níí fi ilẹ̀ (Misrọ) sílẹ̀ títí bàbá mi yóò fi yọ̀ǹda fún mi tàbí (títí) Allāhu yóò fi ṣe ìdájọ́ fún mi. Ó sì lóore jùlọ nínú àwọn olùdájọ́.

Verse 81

ٱرْجِعُوٓا۟ إِلَىٰٓ أَبِيكُمْ فَقُولُوا۟ يَـٰٓأَبَانَآ إِنَّ ٱبْنَكَ سَرَقَ وَمَا شَهِدْنَآ إِلَّا بِمَا عَلِمْنَا وَمَا كُنَّا لِلْغَيْبِ حَـٰفِظِينَ

Transliteration ir'jiʿū ilā abīkum faqūlū yāabānā inna ib'naka saraqa wamā shahid'nā illā bimā ʿalim'nā wamā kunnā lil'ghaybi ḥāfiẓīna

Yoruba Ẹ padà sọ́dọ̀ bàbá yín, kí ẹ sì sọ pé: “Bàbá wa, dájúdájú ọmọ rẹ jalè. A kò sì lè jẹ́rìí (sí kiní kan) àfi ohun tí a bá nímọ̀ (nípa) rẹ̀. Àwa sì kọ́ ni à ń ṣọ ìkọ̀kọ̀ (ẹ̀dá).

Verse 82

وَسْـَٔلِ ٱلْقَرْيَةَ ٱلَّتِى كُنَّا فِيهَا وَٱلْعِيرَ ٱلَّتِىٓ أَقْبَلْنَا فِيهَا ۖ وَإِنَّا لَصَـٰدِقُونَ

Transliteration wasali l-qaryata allatī kunnā fīhā wal-ʿīra allatī aqbalnā fīhā wa-innā laṣādiqūna

Yoruba Kí o sì bi àwọn ará ìlú tí a wà nínú rẹ̀ àti èrò-ràkúnmí tí a jọ darí dé léèrè wò. Dájúdájú olódodo ni wá.”

Verse 83

قَالَ بَلْ سَوَّلَتْ لَكُمْ أَنفُسُكُمْ أَمْرًا ۖ فَصَبْرٌ جَمِيلٌ ۖ عَسَى ٱللَّهُ أَن يَأْتِيَنِى بِهِمْ جَمِيعًا ۚ إِنَّهُۥ هُوَ ٱلْعَلِيمُ ٱلْحَكِيمُ

Transliteration qāla bal sawwalat lakum anfusukum amran faṣabrun jamīlun ʿasā l-lahu an yatiyanī bihim jamīʿan innahu huwa l-ʿalīmu l-ḥakīmu

Yoruba (Ànábì Ya‘ƙūb) sọ pé: “Rárá o, ẹ̀mí yín ló ṣe ọ̀ràn kan lọ́ṣọ̀ọ́ fún yín. Nítorí náà, sùúrù tó rẹwà (lọ̀rọ̀ mi kàn báyìí). Ó ṣeé ṣe kí Allāhu bá mi mú gbogbo wọn wá. Dájúdájú Allāhu, Òun ni Onímọ̀, Ọlọ́gbọ́n.”

Verse 84

وَتَوَلَّىٰ عَنْهُمْ وَقَالَ يَـٰٓأَسَفَىٰ عَلَىٰ يُوسُفَ وَٱبْيَضَّتْ عَيْنَاهُ مِنَ ٱلْحُزْنِ فَهُوَ كَظِيمٌ

Transliteration watawallā ʿanhum waqāla yāasafā ʿalā yūsufa wa-ib'yaḍḍat ʿaynāhu mina l-ḥuz'ni fahuwa kaẓīmun

Yoruba Ó pa wọ́n tì, ó sì sọ pé: “Ìbànújẹ́ ń bẹ fún mi lórí Yūsuf!” Ojú rẹ̀ méjèèjì sì funfun wá (kò ríran mọ́) látara ìbànújẹ́ náà; ó sì pa á mọ́ra.

Verse 85

قَالُوا۟ تَٱللَّهِ تَفْتَؤُا۟ تَذْكُرُ يُوسُفَ حَتَّىٰ تَكُونَ حَرَضًا أَوْ تَكُونَ مِنَ ٱلْهَـٰلِكِينَ

Transliteration qālū tal-lahi tafta-u tadhkuru yūsufa ḥattā takūna ḥaraḍan aw takūna mina l-hālikīna

Yoruba Wọ́n sọ pé: “A fi Allāhu búra, ìwọ kò yé rántí Yūsuf títí o máa fi di yánnayànna tàbí (títí) o máa fi di ara àwọn òkú.”

Verse 86

قَالَ إِنَّمَآ أَشْكُوا۟ بَثِّى وَحُزْنِىٓ إِلَى ٱللَّهِ وَأَعْلَمُ مِنَ ٱللَّهِ مَا لَا تَعْلَمُونَ

Transliteration qāla innamā ashkū bathī waḥuz'nī ilā l-lahi wa-aʿlamu mina l-lahi mā lā taʿlamūna

Yoruba Ó sọ pé: “Allāhu mà ni èmi ń ro ẹ̀dùn ọkàn mi àti ìbànújẹ́ mi fún. Mo sì mọ ohun tí ẹ kò mọ̀ nípa Allāhu.

Verse 87

يَـٰبَنِىَّ ٱذْهَبُوا۟ فَتَحَسَّسُوا۟ مِن يُوسُفَ وَأَخِيهِ وَلَا تَا۟يْـَٔسُوا۟ مِن رَّوْحِ ٱللَّهِ ۖ إِنَّهُۥ لَا يَا۟يْـَٔسُ مِن رَّوْحِ ٱللَّهِ إِلَّا ٱلْقَوْمُ ٱلْكَـٰفِرُونَ

Transliteration yābaniyya idh'habū fataḥassasū min yūsufa wa-akhīhi walā tāy'asū min rawḥi l-lahi innahu lā yāy'asu min rawḥi l-lahi illā l-qawmu l-kāfirūna

Yoruba Ẹ̀yin ọmọ mi, ẹ lọ wádìí nípa Yūsuf àti ọmọ-ìyá rẹ̀. Ẹ sì má ṣe sọ̀rètí nù nínú ìkẹ́ Allāhu. Dájúdájú kò sí ẹnì kan tí ó máa sọ̀rètí nù nínú ìkẹ́ Allāhu àfi ìjọ aláìgbàgbọ́.”

Verse 88

فَلَمَّا دَخَلُوا۟ عَلَيْهِ قَالُوا۟ يَـٰٓأَيُّهَا ٱلْعَزِيزُ مَسَّنَا وَأَهْلَنَا ٱلضُّرُّ وَجِئْنَا بِبِضَـٰعَةٍ مُّزْجَىٰةٍ فَأَوْفِ لَنَا ٱلْكَيْلَ وَتَصَدَّقْ عَلَيْنَآ ۖ إِنَّ ٱللَّهَ يَجْزِى ٱلْمُتَصَدِّقِينَ

Transliteration falammā dakhalū ʿalayhi qālū yāayyuhā l-ʿazīzu massanā wa-ahlanā l-ḍuru waji'nā bibiḍāʿatin muz'jātin fa-awfi lanā l-kayla wataṣaddaq ʿalaynā inna l-laha yajzī l-mutaṣadiqīna

Yoruba Nìgbà tí wọ́n wọlé tọ Yūsuf, wọ́n sọ pé: “Ìwọ ọba, ìnira (ebi) ti mú àwa àti ará ilé wa. A sì mú owó kan tí ẹ máa ta dànù lọ́wọ́.Nítorí náà, wọn kóńgò (oúnjẹ) náà kún fún wa, kí ó sì ta wá lọ́rẹ. Dájúdájú Allāhu yóò san àwọn olùtọrẹ ní ẹ̀san rere.”

Verse 89

قَالَ هَلْ عَلِمْتُم مَّا فَعَلْتُم بِيُوسُفَ وَأَخِيهِ إِذْ أَنتُمْ جَـٰهِلُونَ

Transliteration qāla hal ʿalim'tum mā faʿaltum biyūsufa wa-akhīhi idh antum jāhilūna

Yoruba Ó sọ pé: “Ǹjẹ́ ẹ mọ ohun tí ẹ ṣe fún Yūsuf àti ọmọ ìyá rẹ̀ nígbà tí ẹ̀yin jẹ́ aláìmọ̀kan?”

Verse 90

قَالُوٓا۟ أَءِنَّكَ لَأَنتَ يُوسُفُ ۖ قَالَ أَنَا۠ يُوسُفُ وَهَـٰذَآ أَخِى ۖ قَدْ مَنَّ ٱللَّهُ عَلَيْنَآ ۖ إِنَّهُۥ مَن يَتَّقِ وَيَصْبِرْ فَإِنَّ ٱللَّهَ لَا يُضِيعُ أَجْرَ ٱلْمُحْسِنِينَ

Transliteration qālū a-innaka la-anta yūsufu qāla anā yūsufu wahādhā akhī qad manna l-lahu ʿalaynā innahu man yattaqi wayaṣbir fa-inna l-laha lā yuḍīʿu ajra l-muḥ'sinīna

Yoruba Wọ́n sọ pé: “Ṣé dájúdájú ìwọ ni Yūsuf?” Ó sọ pé: “Èmi ni Yūsuf. Ọmọ ìyá mi sì nìyí. Dájúdájú Allāhu ti ṣe ìdẹ̀ra fún wa. Dájúdájú ẹnikẹ́ni tí ó bá bẹ̀rù (Allāhu), tí ó sì ṣe sùúrù, dájúdájú Allāhu kò níí fi ẹ̀san àwọn olùṣe-rere ráre.”

Verse 91

قَالُوا۟ تَٱللَّهِ لَقَدْ ءَاثَرَكَ ٱللَّهُ عَلَيْنَا وَإِن كُنَّا لَخَـٰطِـِٔينَ

Transliteration qālū tal-lahi laqad ātharaka l-lahu ʿalaynā wa-in kunnā lakhāṭiīna

Yoruba Wọ́n sọ pé: “A fi Allāhu búra! Dájúdájú Allāhu ti gbọ́lá fún ọ jù wá lọ. Àti pé dájúdájú àwa ni aláṣìṣe.”

Verse 92

قَالَ لَا تَثْرِيبَ عَلَيْكُمُ ٱلْيَوْمَ ۖ يَغْفِرُ ٱللَّهُ لَكُمْ ۖ وَهُوَ أَرْحَمُ ٱلرَّٰحِمِينَ

Transliteration qāla lā tathrība ʿalaykumu l-yawma yaghfiru l-lahu lakum wahuwa arḥamu l-rāḥimīna

Yoruba Ó sọ pé: “Kò sí ìbáwí fún yín ní òní. Allāhu yóò foríjìn yín. Òun sì ni Aláàánú-jùlọ nínú àwọn aláàánú.

Verse 93

ٱذْهَبُوا۟ بِقَمِيصِى هَـٰذَا فَأَلْقُوهُ عَلَىٰ وَجْهِ أَبِى يَأْتِ بَصِيرًا وَأْتُونِى بِأَهْلِكُمْ أَجْمَعِينَ

Transliteration idh'habū biqamīṣī hādhā fa-alqūhu ʿalā wajhi abī yati baṣīran watūnī bi-ahlikum ajmaʿīna

Yoruba Ẹ mú ẹ̀wù mi yìí lọ, kí ẹ fi lé iwájú bàbá mi, ó máa padà di olùríran. Kí ẹ sì kó gbogbo ẹbí yín wá bá mi.”

Verse 94

وَلَمَّا فَصَلَتِ ٱلْعِيرُ قَالَ أَبُوهُمْ إِنِّى لَأَجِدُ رِيحَ يُوسُفَ ۖ لَوْلَآ أَن تُفَنِّدُونِ

Transliteration walammā faṣalati l-ʿīru qāla abūhum innī la-ajidu rīḥa yūsufa lawlā an tufannidūni

Yoruba Nígbà tí èrò-ràkúnmí náà sí pínyà (kúrò lọ́dọ̀ Ànábì Yūsuf), bàbá wọn sọ pé: “Dájúdájú èmi ń gbọ́ òórùn Yūsuf tí ẹ kò bá níí sọ pé mò ń jarán.”

Verse 95

قَالُوا۟ تَٱللَّهِ إِنَّكَ لَفِى ضَلَـٰلِكَ ٱلْقَدِيمِ

Transliteration qālū tal-lahi innaka lafī ḍalālika l-qadīmi

Yoruba Wọ́n sọ pé: “A fi Allāhu búra! Dájúdájú ìwọ sì wà nínú àṣìṣe rẹ ti àtijọ́ (nípa ìfẹ́ Yūsuf).”

Verse 96

فَلَمَّآ أَن جَآءَ ٱلْبَشِيرُ أَلْقَىٰهُ عَلَىٰ وَجْهِهِۦ فَٱرْتَدَّ بَصِيرًا ۖ قَالَ أَلَمْ أَقُل لَّكُمْ إِنِّىٓ أَعْلَمُ مِنَ ٱللَّهِ مَا لَا تَعْلَمُونَ

Transliteration falammā an jāa l-bashīru alqāhu ʿalā wajhihi fa-ir'tadda baṣīran qāla alam aqul lakum innī aʿlamu mina l-lahi mā lā taʿlamūna

Yoruba Nígbà tí oníròó-ìdùnnú dé, ó ju (ẹ̀wù náà) lé e níwájú, ó sì ríran padà. Ó sọ pé: “Ǹjẹ́ èmi kò sọ fún yín pé dájúdájú mo mọ ohun tí ẹ kò mọ̀ nípa Allāhu.”

Verse 97

قَالُوا۟ يَـٰٓأَبَانَا ٱسْتَغْفِرْ لَنَا ذُنُوبَنَآ إِنَّا كُنَّا خَـٰطِـِٔينَ

Transliteration qālū yāabānā is'taghfir lanā dhunūbanā innā kunnā khāṭiīna

Yoruba Wọ́n sọ pé: “Bàbá wa, tọrọ àforíjìn ẹ̀ṣẹ̀ wa fún wa, dájúdájú àwa jẹ́ aláṣìṣe.”

Verse 98

قَالَ سَوْفَ أَسْتَغْفِرُ لَكُمْ رَبِّىٓ ۖ إِنَّهُۥ هُوَ ٱلْغَفُورُ ٱلرَّحِيمُ

Transliteration qāla sawfa astaghfiru lakum rabbī innahu huwa l-ghafūru l-raḥīmu

Yoruba Ó sọ pé: “Láìpẹ́ mo máa tọrọ àforíjìn fún yín lọ́dọ̀ Olúwa mi. Dájúdájú Allāhu, Òun ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.”

Verse 99

فَلَمَّا دَخَلُوا۟ عَلَىٰ يُوسُفَ ءَاوَىٰٓ إِلَيْهِ أَبَوَيْهِ وَقَالَ ٱدْخُلُوا۟ مِصْرَ إِن شَآءَ ٱللَّهُ ءَامِنِينَ

Transliteration falammā dakhalū ʿalā yūsufa āwā ilayhi abawayhi waqāla ud'khulū miṣ'ra in shāa l-lahu āminīna

Yoruba Nígbà tí wọ́n wọlé tọ (Ànábì) Yūsuf, ó kó àwọn òbí rẹ̀ méjèèjì mọ́ra sọ́dọ̀ rẹ̀, ó sì sọ pé: “Ẹ wọ ìlú Misrọ ní olùfàyàbalẹ̀ - tí Allāhu bá fẹ́.-”

Verse 100

وَرَفَعَ أَبَوَيْهِ عَلَى ٱلْعَرْشِ وَخَرُّوا۟ لَهُۥ سُجَّدًا ۖ وَقَالَ يَـٰٓأَبَتِ هَـٰذَا تَأْوِيلُ رُءْيَـٰىَ مِن قَبْلُ قَدْ جَعَلَهَا رَبِّى حَقًّا ۖ وَقَدْ أَحْسَنَ بِىٓ إِذْ أَخْرَجَنِى مِنَ ٱلسِّجْنِ وَجَآءَ بِكُم مِّنَ ٱلْبَدْوِ مِنۢ بَعْدِ أَن نَّزَغَ ٱلشَّيْطَـٰنُ بَيْنِى وَبَيْنَ إِخْوَتِىٓ ۚ إِنَّ رَبِّى لَطِيفٌ لِّمَا يَشَآءُ ۚ إِنَّهُۥ هُوَ ٱلْعَلِيمُ ٱلْحَكِيمُ

Transliteration warafaʿa abawayhi ʿalā l-ʿarshi wakharrū lahu sujjadan waqāla yāabati hādhā tawīlu ru'yāya min qablu qad jaʿalahā rabbī ḥaqqan waqad aḥsana bī idh akhrajanī mina l-sij'ni wajāa bikum mina l-badwi min baʿdi an nazagha l-shayṭānu baynī wabayna ikh'watī inna rabbī laṭīfun limā yashāu innahu huwa l-ʿalīmu l-ḥakīmu

Yoruba Ó gbé àwọn òbí rẹ̀ méjèèjì sórí ìtẹ́. Wọ́n sì wó lulẹ̀ fún un, tí wọ́n forí kanlẹ̀ kí i.Ó sọ pé: “Bàbá mi, èyí ni ìtúmọ̀ àlá mi (tí mo lá) ṣíwájú. Dájúdájú Olúwa mi ti sọ ọ́ di òdodo. Ó sì ṣe dáadáa fún mi nígbà tí Ó mú mi jáde kúrò nínú ọgbà ẹ̀wọ̀n. Ó tún mu yín wá (bá mi) láti inú oko lẹ́yìn tí Èṣù ti saburú sáààrin èmi àti àwọn ọbà-kan mi. Dájúdájú Olúwa mi ni Aláàánú fún ohun tí Ó bá fẹ́. Dájúdájú Allāhu, Òun ni Onímọ̀, Ọlọ́gbọ́n.

Verse 101

۞ رَبِّ قَدْ ءَاتَيْتَنِى مِنَ ٱلْمُلْكِ وَعَلَّمْتَنِى مِن تَأْوِيلِ ٱلْأَحَادِيثِ ۚ فَاطِرَ ٱلسَّمَـٰوَٰتِ وَٱلْأَرْضِ أَنتَ وَلِىِّۦ فِى ٱلدُّنْيَا وَٱلْـَٔاخِرَةِ ۖ تَوَفَّنِى مُسْلِمًا وَأَلْحِقْنِى بِٱلصَّـٰلِحِينَ

Transliteration rabbi qad ātaytanī mina l-mul'ki waʿallamtanī min tawīli l-aḥādīthi fāṭira l-samāwāti wal-arḍi anta waliyyī fī l-dun'yā wal-ākhirati tawaffanī mus'liman wa-alḥiq'nī bil-ṣāliḥīna

Yoruba Olúwa mi, dájúdájú O ti fún mi nínú ìjọba. O tún fún mi nínú ìmọ̀ ìtúmọ̀ àlá. Olùpilẹ̀dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀, Ìwọ ni Alátìlẹ́yìn mi ní ayé àti ní ọ̀run, pa mí sípò mùsùlùmí. Kí O sì fi mí pẹ̀lú àwọn ẹni rere.”

Verse 102

ذَٰلِكَ مِنْ أَنۢبَآءِ ٱلْغَيْبِ نُوحِيهِ إِلَيْكَ ۖ وَمَا كُنتَ لَدَيْهِمْ إِذْ أَجْمَعُوٓا۟ أَمْرَهُمْ وَهُمْ يَمْكُرُونَ

Transliteration dhālika min anbāi l-ghaybi nūḥīhi ilayka wamā kunta ladayhim idh ajmaʿū amrahum wahum yamkurūna

Yoruba Ìyẹn wà nínú ìró ìkọ̀kọ̀ tí A fi ìmísí (rẹ̀) ránṣẹ́ sí ọ. Àti pé ìwọ kò sí lọ́dọ̀ wọn nígbà tí wọ́n fẹnukò lórí ọ̀rọ̀ wọn, tí wọ́n ń déte.

Verse 103

وَمَآ أَكْثَرُ ٱلنَّاسِ وَلَوْ حَرَصْتَ بِمُؤْمِنِينَ

Transliteration wamā aktharu l-nāsi walaw ḥaraṣta bimu'minīna

Yoruba Ìwọ ìbáà ṣojú kòkòrò (ìgbàlà wọn), ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ènìyàn ni kò níí gbàgbọ́.

Verse 104

وَمَا تَسْـَٔلُهُمْ عَلَيْهِ مِنْ أَجْرٍ ۚ إِنْ هُوَ إِلَّا ذِكْرٌ لِّلْعَـٰلَمِينَ

Transliteration wamā tasaluhum ʿalayhi min ajrin in huwa illā dhik'run lil'ʿālamīna

Yoruba Ìwọ kò sì bi wọ́n léèrè owó-ọ̀yà kan lórí rẹ̀. Kò sì jẹ́ kiní kan bí kò ṣe ìrántí fún gbogbo ẹ̀dá.

Verse 105

وَكَأَيِّن مِّنْ ءَايَةٍ فِى ٱلسَّمَـٰوَٰتِ وَٱلْأَرْضِ يَمُرُّونَ عَلَيْهَا وَهُمْ عَنْهَا مُعْرِضُونَ

Transliteration waka-ayyin min āyatin fī l-samāwāti wal-arḍi yamurrūna ʿalayhā wahum ʿanhā muʿ'riḍūna

Yoruba Àti pé mélòó mélòó nínú àwọn àmì tí ń bẹ ní sánmọ̀ àti ní orí ilẹ̀ tí wọ́n ń ré kọjá lórí rẹ̀, tí wọ́n sì ń gbúnrí kúrò níbẹ̀.

Verse 106

وَمَا يُؤْمِنُ أَكْثَرُهُم بِٱللَّهِ إِلَّا وَهُم مُّشْرِكُونَ

Transliteration wamā yu'minu aktharuhum bil-lahi illā wahum mush'rikūna

Yoruba Ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn sì ni kò níí gbàgbọ́ nínú Allāhu àfi kí wọ́n tún máa ṣẹbọ.1

Verse 107

أَفَأَمِنُوٓا۟ أَن تَأْتِيَهُمْ غَـٰشِيَةٌ مِّنْ عَذَابِ ٱللَّهِ أَوْ تَأْتِيَهُمُ ٱلسَّاعَةُ بَغْتَةً وَهُمْ لَا يَشْعُرُونَ

Transliteration afa-aminū an tatiyahum ghāshiyatun min ʿadhābi l-lahi aw tatiyahumu l-sāʿatu baghtatan wahum lā yashʿurūna

Yoruba Ṣé wọ́n fàyà balẹ̀ pé ohun tí ń bo ẹ̀dá mọ́lẹ̀ nínú ìyà Allāhu kò lè dé bá àwọn ni tàbí pé Àkókò náà kò lè kò lé àwọn lórí ní òjijì, tí wọn kò sì níí fura?

Verse 108

قُلْ هَـٰذِهِۦ سَبِيلِىٓ أَدْعُوٓا۟ إِلَى ٱللَّهِ ۚ عَلَىٰ بَصِيرَةٍ أَنَا۠ وَمَنِ ٱتَّبَعَنِى ۖ وَسُبْحَـٰنَ ٱللَّهِ وَمَآ أَنَا۠ مِنَ ٱلْمُشْرِكِينَ

Transliteration qul hādhihi sabīlī adʿū ilā l-lahi ʿalā baṣīratin anā wamani ittabaʿanī wasub'ḥāna l-lahi wamā anā mina l-mush'rikīna

Yoruba Sọ pé: “Èyí ni ojú ọ̀nà (ẹ̀sìn) mi, èmi àti àwọn tó tẹ̀lé mi sì ń pèpè sí (ẹ̀sìn) Allāhu pẹ̀lú ìmọ̀ àmọ̀dájú àti ẹ̀rí. Mímọ́ ni fún Allāhu. Èmi kò sì sí lára àwọn ọ̀ṣẹbọ.”

Verse 109

وَمَآ أَرْسَلْنَا مِن قَبْلِكَ إِلَّا رِجَالًا نُّوحِىٓ إِلَيْهِم مِّنْ أَهْلِ ٱلْقُرَىٰٓ ۗ أَفَلَمْ يَسِيرُوا۟ فِى ٱلْأَرْضِ فَيَنظُرُوا۟ كَيْفَ كَانَ عَـٰقِبَةُ ٱلَّذِينَ مِن قَبْلِهِمْ ۗ وَلَدَارُ ٱلْـَٔاخِرَةِ خَيْرٌ لِّلَّذِينَ ٱتَّقَوْا۟ ۗ أَفَلَا تَعْقِلُونَ

Transliteration wamā arsalnā min qablika illā rijālan nūḥī ilayhim min ahli l-qurā afalam yasīrū fī l-arḍi fayanẓurū kayfa kāna ʿāqibatu alladhīna min qablihim waladāru l-ākhirati khayrun lilladhīna ittaqaw afalā taʿqilūna

Yoruba A kò rán ẹnì kan ní iṣẹ́-òjíṣẹ́ ṣíwájú rẹ àfi àwọn ọkùnrin tí À ń fi ìmísí ránṣẹ́ sí nínú àwọn ará ìlú.Ṣé wọn kò rìn kiri lórí ilẹ̀ kí wọ́n wo bí ìkángun àwọn tó ṣíwájú wọn ṣe rí? Dájúdájú Ilé ìkẹ́yìn lóore jùlọ fún àwọn tó bẹ̀rù (Allāhu). Ṣé ẹ ò ṣe làákàyè ni?

Verse 110

حَتَّىٰٓ إِذَا ٱسْتَيْـَٔسَ ٱلرُّسُلُ وَظَنُّوٓا۟ أَنَّهُمْ قَدْ كُذِبُوا۟ جَآءَهُمْ نَصْرُنَا فَنُجِّىَ مَن نَّشَآءُ ۖ وَلَا يُرَدُّ بَأْسُنَا عَنِ ٱلْقَوْمِ ٱلْمُجْرِمِينَ

Transliteration ḥattā idhā is'tayasa l-rusulu waẓannū annahum qad kudhibū jāahum naṣrunā fanujjiya man nashāu walā yuraddu basunā ʿani l-qawmi l-muj'rimīna

Yoruba (A kì í jẹ àwọn ènìyàn níyà) títí di ìgbà tí àwọn Òjíṣẹ́ bá tó sọ̀rètí nù (nípa ìgbàgbọ́ wọn), tí wọ́n sì mọ̀ pé wọ́n ti pe àwọn ní òpùrọ́. Àrànṣe Wa yó sì dé bá wọn. A sì máa gba ẹni tí A bá fẹ́ là. Wọn kò lè dá ìyà Wa padà lórí ìjọ ẹlẹ́ṣẹ̀.

Verse 111

لَقَدْ كَانَ فِى قَصَصِهِمْ عِبْرَةٌ لِّأُو۟لِى ٱلْأَلْبَـٰبِ ۗ مَا كَانَ حَدِيثًا يُفْتَرَىٰ وَلَـٰكِن تَصْدِيقَ ٱلَّذِى بَيْنَ يَدَيْهِ وَتَفْصِيلَ كُلِّ شَىْءٍ وَهُدًى وَرَحْمَةً لِّقَوْمٍ يُؤْمِنُونَ

Transliteration laqad kāna fī qaṣaṣihim ʿib'ratun li-ulī l-albābi mā kāna ḥadīthan yuf'tarā walākin taṣdīqa alladhī bayna yadayhi watafṣīla kulli shayin wahudan waraḥmatan liqawmin yu'minūna

Yoruba Dájúdájú àríwòye wà nínú ìtàn wọn fún àwọn onílàákàyè. (Al-Ƙur’ān) kì í ṣe ọ̀rọ̀ kan tí wọ́n ń hun, ṣùgbọ́n ó ń jẹ́rìí sí èyí tó jẹ́ òdodo nínú èyí tó ṣíwájú rẹ̀, ó ń ṣàlàyé gbogbo n̄ǹkan;ó jẹ́ ìmọ̀nà àti ìkẹ́ fún ìjọ onígbàgbọ́ òdodo.

Read Surah Yusuf in another language

All languages

All 114 surahs in Yoruba: the Qur’an in Yoruba.

Learn it in MyDugsi

Yoruba translation: Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni, from Quran.com. Transliteration: Quran.com. Recitation: Mishary Alafasy, from EveryAyah.com. MyDugsi is a learning aid, not a replacement for a qualified teacher.