Surah Yunus in Yoruba: translation and audio
Surah 10 · يونس · Jonah · 109 verses
Surah Yunus verse by verse: the Arabic with a recitation you can repeat, the transliteration, and the Yoruba translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni. For the meaning of every word, see Surah Yunus word by word in English.
Verse 1
الٓر ۚ تِلْكَ ءَايَـٰتُ ٱلْكِتَـٰبِ ٱلْحَكِيمِ
Transliteration alif-lam-ra til'ka āyātu l-kitābi l-ḥakīmi
Yoruba ’Alif Lām Rọ̄. (Allāhu ló mọ ohun tí Ó gbàlérò pẹ̀lú àwọn háràfí náà.)Ìwọ̀nyí ni àwọn āyah Tírà tí ó kún fún ọgbọ́n.2
Verse 2
أَكَانَ لِلنَّاسِ عَجَبًا أَنْ أَوْحَيْنَآ إِلَىٰ رَجُلٍ مِّنْهُمْ أَنْ أَنذِرِ ٱلنَّاسَ وَبَشِّرِ ٱلَّذِينَ ءَامَنُوٓا۟ أَنَّ لَهُمْ قَدَمَ صِدْقٍ عِندَ رَبِّهِمْ ۗ قَالَ ٱلْكَـٰفِرُونَ إِنَّ هَـٰذَا لَسَـٰحِرٌ مُّبِينٌ
Transliteration akāna lilnnāsi ʿajaban an awḥaynā ilā rajulin min'hum an andhiri l-nāsa wabashiri alladhīna āmanū anna lahum qadama ṣid'qin ʿinda rabbihim qāla l-kāfirūna inna hādhā lasāḥirun mubīnun
Yoruba Ṣé ó jẹ́ kàyééfì fún àwọn ènìyàn pé A fi ìmísí ránṣẹ́ sí arákùnrin kan nínú wọn pé: “Ṣe ìkìlọ̀ fún àwọn ènìyàn, kí o sì fún àwọn tó gbàgbọ́ ní ìró ìdùnnú pé ẹ̀san rere (iṣẹ́ tí wọ́n ṣe) ṣíwájú ti wà ní ọ̀dọ̀ Olúwa wọn.”? Àwọn aláìgbàgbọ́ wí pé: “Dájúdájú òpìdán pọ́nńbélé mà ni (Ànábì) yìí.”
Verse 3
إِنَّ رَبَّكُمُ ٱللَّهُ ٱلَّذِى خَلَقَ ٱلسَّمَـٰوَٰتِ وَٱلْأَرْضَ فِى سِتَّةِ أَيَّامٍ ثُمَّ ٱسْتَوَىٰ عَلَى ٱلْعَرْشِ ۖ يُدَبِّرُ ٱلْأَمْرَ ۖ مَا مِن شَفِيعٍ إِلَّا مِنۢ بَعْدِ إِذْنِهِۦ ۚ ذَٰلِكُمُ ٱللَّهُ رَبُّكُمْ فَٱعْبُدُوهُ ۚ أَفَلَا تَذَكَّرُونَ
Transliteration inna rabbakumu l-lahu alladhī khalaqa l-samāwāti wal-arḍa fī sittati ayyāmin thumma is'tawā ʿalā l-ʿarshi yudabbiru l-amra mā min shafīʿin illā min baʿdi idh'nihi dhālikumu l-lahu rabbukum fa-uʿ'budūhu afalā tadhakkarūna
Yoruba Dájúdájú Olúwa yín ni Allāhu, Ẹni tí Ó ṣẹ̀dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ fún ọjọ́ mẹ́fà. Lẹ́yìn náà, Ó gúnwà sí orí Ìtẹ́-ọlá. Ó ń ṣètò ọ̀rọ̀ (ẹ̀dá). Kò sí olùṣìpẹ̀ kan àfi lẹ́yìn ìyọ̀ǹda Rẹ̀. Ìyẹn ni Allāhu, Olúwa yín. Nítorí náà, ẹ jọ́sìn fún Un. Ṣé ẹ ò níí lo ìrántí ni?
Verse 4
إِلَيْهِ مَرْجِعُكُمْ جَمِيعًا ۖ وَعْدَ ٱللَّهِ حَقًّا ۚ إِنَّهُۥ يَبْدَؤُا۟ ٱلْخَلْقَ ثُمَّ يُعِيدُهُۥ لِيَجْزِىَ ٱلَّذِينَ ءَامَنُوا۟ وَعَمِلُوا۟ ٱلصَّـٰلِحَـٰتِ بِٱلْقِسْطِ ۚ وَٱلَّذِينَ كَفَرُوا۟ لَهُمْ شَرَابٌ مِّنْ حَمِيمٍ وَعَذَابٌ أَلِيمٌۢ بِمَا كَانُوا۟ يَكْفُرُونَ
Transliteration ilayhi marjiʿukum jamīʿan waʿda l-lahi ḥaqqan innahu yabda-u l-khalqa thumma yuʿīduhu liyajziya alladhīna āmanū waʿamilū l-ṣāliḥāti bil-qis'ṭi wa-alladhīna kafarū lahum sharābun min ḥamīmin waʿadhābun alīmun bimā kānū yakfurūna
Yoruba Ọ̀dọ̀ Rẹ̀ ni ibùpadàsí gbogbo yín. (Ó jẹ́) àdéhùn Allāhu ní ti òdodo. Dájúdájú Òun l’Ó ń pilẹ̀ dídá ẹ̀dá. Lẹ́yìn náà, Ó máa da á padà (sọ́dọ̀ Rẹ̀) nítorí kí Ó lè fi déédé san ẹ̀san fún àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe iṣẹ́ rere. Àwọn tó sì ṣàì gbàgbọ́, ohun mímu tó gbóná parí àti ìyà ẹlẹ́ta-eléro ń bẹ fún wọn nítorí pé, wọ́n ṣàì gbàgbọ́.
Verse 5
هُوَ ٱلَّذِى جَعَلَ ٱلشَّمْسَ ضِيَآءً وَٱلْقَمَرَ نُورًا وَقَدَّرَهُۥ مَنَازِلَ لِتَعْلَمُوا۟ عَدَدَ ٱلسِّنِينَ وَٱلْحِسَابَ ۚ مَا خَلَقَ ٱللَّهُ ذَٰلِكَ إِلَّا بِٱلْحَقِّ ۚ يُفَصِّلُ ٱلْـَٔايَـٰتِ لِقَوْمٍ يَعْلَمُونَ
Transliteration huwa alladhī jaʿala l-shamsa ḍiyāan wal-qamara nūran waqaddarahu manāzila litaʿlamū ʿadada l-sinīna wal-ḥisāba mā khalaqa l-lahu dhālika illā bil-ḥaqi yufaṣṣilu l-āyāti liqawmin yaʿlamūna
Yoruba (Allāhu) Òun ni Ẹni tí Ó ṣe òòrùn ní ìtànsán. (Ó ṣe) òṣùpá ní ìmọ́lẹ̀. Ó sì díwọ̀n (ìrísí) rẹ̀ sínú àwọn ibùsọ̀ nítorí kí ẹ lè mọ òǹkà àwọn ọdún àti ìṣírò (ọjọ́). Allāhu kò dá ìyẹn bí kò ṣe pẹ̀lú òdodo. Ó ń ṣàlàyé àwọn āyah fún ìjọ tó nímọ̀.
Verse 6
إِنَّ فِى ٱخْتِلَـٰفِ ٱلَّيْلِ وَٱلنَّهَارِ وَمَا خَلَقَ ٱللَّهُ فِى ٱلسَّمَـٰوَٰتِ وَٱلْأَرْضِ لَـَٔايَـٰتٍ لِّقَوْمٍ يَتَّقُونَ
Transliteration inna fī ikh'tilāfi al-layli wal-nahāri wamā khalaqa l-lahu fī l-samāwāti wal-arḍi laāyātin liqawmin yattaqūna
Yoruba Dájúdájú àwọn àmì wà nínú ìtẹ̀léǹtẹ̀lé òru àti ọ̀sán àti ohun tí Allāhu dá sínú àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀; (àmì wà nínú wọn) fún ìjọ tó ń bẹ̀rù (Allāhu).
Verse 7
إِنَّ ٱلَّذِينَ لَا يَرْجُونَ لِقَآءَنَا وَرَضُوا۟ بِٱلْحَيَوٰةِ ٱلدُّنْيَا وَٱطْمَأَنُّوا۟ بِهَا وَٱلَّذِينَ هُمْ عَنْ ءَايَـٰتِنَا غَـٰفِلُونَ
Transliteration inna alladhīna lā yarjūna liqāanā waraḍū bil-ḥayati l-dun'yā wa-iṭ'ma-annū bihā wa-alladhīna hum ʿan āyātinā ghāfilūna
Yoruba Dájúdájú àwọn tí kò retí ìpàdé Wa (ní ọ̀run), tí wọ́n yọ́nú sí ìṣẹ̀mí ayé, tí ọkàn wọn sì balẹ̀ dódó sí (ìṣẹ̀mí ayé yìí) àti àwọn afọ́nú-fọ́ra nípa àwọn āyah Wa,
Verse 8
أُو۟لَـٰٓئِكَ مَأْوَىٰهُمُ ٱلنَّارُ بِمَا كَانُوا۟ يَكْسِبُونَ
Transliteration ulāika mawāhumu l-nāru bimā kānū yaksibūna
Yoruba àwọn wọ̀nyẹn, ibùgbé wọn ni Iná nítorí ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́.
Verse 9
إِنَّ ٱلَّذِينَ ءَامَنُوا۟ وَعَمِلُوا۟ ٱلصَّـٰلِحَـٰتِ يَهْدِيهِمْ رَبُّهُم بِإِيمَـٰنِهِمْ ۖ تَجْرِى مِن تَحْتِهِمُ ٱلْأَنْهَـٰرُ فِى جَنَّـٰتِ ٱلنَّعِيمِ
Transliteration inna alladhīna āmanū waʿamilū l-ṣāliḥāti yahdīhim rabbuhum biīmānihim tajrī min taḥtihimu l-anhāru fī jannāti l-naʿīmi
Yoruba Dájúdájú àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe àwọn iṣẹ́ rere, Olúwa wọn yóò fi ìgbàgbọ́ òdodo wọn tọ́ wọn sọ́nà.Àwọn odò yó sì máa ṣàn ní ìsàlẹ̀ ọ̀dọ̀ wọn nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra.
Verse 10
دَعْوَىٰهُمْ فِيهَا سُبْحَـٰنَكَ ٱللَّهُمَّ وَتَحِيَّتُهُمْ فِيهَا سَلَـٰمٌ ۚ وَءَاخِرُ دَعْوَىٰهُمْ أَنِ ٱلْحَمْدُ لِلَّهِ رَبِّ ٱلْعَـٰلَمِينَ
Transliteration daʿwāhum fīhā sub'ḥānaka l-lahuma wataḥiyyatuhum fīhā salāmun waākhiru daʿwāhum ani l-ḥamdu lillahi rabbi l-ʿālamīna
Yoruba Àdúà wọn nínú rẹ̀ ni “mímọ́ ni fún Ọ, Allāhu”. Ìkíni wọn nínú rẹ̀ ni “àlàáfíà”. Ìparí àdúà wọn sì ni pé, “Gbogbo ẹyìn ń jẹ́ ti Allāhu,Olúwa gbogbo ẹ̀dá.”
Verse 11
۞ وَلَوْ يُعَجِّلُ ٱللَّهُ لِلنَّاسِ ٱلشَّرَّ ٱسْتِعْجَالَهُم بِٱلْخَيْرِ لَقُضِىَ إِلَيْهِمْ أَجَلُهُمْ ۖ فَنَذَرُ ٱلَّذِينَ لَا يَرْجُونَ لِقَآءَنَا فِى طُغْيَـٰنِهِمْ يَعْمَهُونَ
Transliteration walaw yuʿajjilu l-lahu lilnnāsi l-shara is'tiʿ'jālahum bil-khayri laquḍiya ilayhim ajaluhum fanadharu alladhīna lā yarjūna liqāanā fī ṭugh'yānihim yaʿmahūna
Yoruba Tí ó bá jẹ́ pé Allāhu ń kánjú mú aburú bá àwọn ènìyàn (nípasẹ̀ èpè ẹnu wọn, gẹ́gẹ́ bí Ó ṣe ń) tètè mú oore bá wọn (nípasẹ̀ àdúà), A ìbá ti mú òpin ba ìṣẹ́mí wọn. Nítorí náà, A máa fi àwọn tí kò retí ìpàdé Wa sílẹ̀ sínú àgbéré wọn, tí wọn yóò máa pa rìdàrìdà.
Verse 12
وَإِذَا مَسَّ ٱلْإِنسَـٰنَ ٱلضُّرُّ دَعَانَا لِجَنۢبِهِۦٓ أَوْ قَاعِدًا أَوْ قَآئِمًا فَلَمَّا كَشَفْنَا عَنْهُ ضُرَّهُۥ مَرَّ كَأَن لَّمْ يَدْعُنَآ إِلَىٰ ضُرٍّ مَّسَّهُۥ ۚ كَذَٰلِكَ زُيِّنَ لِلْمُسْرِفِينَ مَا كَانُوا۟ يَعْمَلُونَ
Transliteration wa-idhā massa l-insāna l-ḍuru daʿānā lijanbihi aw qāʿidan aw qāiman falammā kashafnā ʿanhu ḍurrahu marra ka-an lam yadʿunā ilā ḍurrin massahu kadhālika zuyyina lil'mus'rifīna mā kānū yaʿmalūna
Yoruba Nígbà tí ìnira bá kan ènìyàn, ó máa pè Wá lórí ìdùbúlẹ̀ rẹ̀ tàbí ní ìjókòó tàbí ní ìnàró. Nígbà tí A bá mú ìnira rẹ̀ kúrò fún un, ó máa tẹ̀ síwájú (nínú àìgbàgbọ́) bí ẹni pé kò pè Wá sí ìnira tí ó mú un. Báyẹn ni wọ́n ṣe ní ọ̀ṣọ́ fún àwọn alákọyọ ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́.
Verse 13
وَلَقَدْ أَهْلَكْنَا ٱلْقُرُونَ مِن قَبْلِكُمْ لَمَّا ظَلَمُوا۟ ۙ وَجَآءَتْهُمْ رُسُلُهُم بِٱلْبَيِّنَـٰتِ وَمَا كَانُوا۟ لِيُؤْمِنُوا۟ ۚ كَذَٰلِكَ نَجْزِى ٱلْقَوْمَ ٱلْمُجْرِمِينَ
Transliteration walaqad ahlaknā l-qurūna min qablikum lammā ẓalamū wajāathum rusuluhum bil-bayināti wamā kānū liyu'minū kadhālika najzī l-qawma l-muj'rimīna
Yoruba A kúkú ti pa àwọn ìran kan rẹ́ ṣíwájú yín nígbà tí wọ́n ṣe àbòsí. Àwọn Òjíṣẹ́ wọn mú àwọn ẹ̀rí tó yanjú wá bá wọn. Wọn kò sì gbàgbọ́. Báyẹn ni A ṣe ń san ìjọ ẹlẹ́ṣẹ̀ ní ẹ̀san.
Verse 14
ثُمَّ جَعَلْنَـٰكُمْ خَلَـٰٓئِفَ فِى ٱلْأَرْضِ مِنۢ بَعْدِهِمْ لِنَنظُرَ كَيْفَ تَعْمَلُونَ
Transliteration thumma jaʿalnākum khalāifa fī l-arḍi min baʿdihim linanẓura kayfa taʿmalūna
Yoruba Lẹ́yìn náà, A ṣe yín ní àrólé lórí ilẹ̀ lẹ́yìn wọn nítorí kí Á lè wo bí ẹ̀yin náà yóò ṣe máa ṣe.
Verse 15
وَإِذَا تُتْلَىٰ عَلَيْهِمْ ءَايَاتُنَا بَيِّنَـٰتٍ ۙ قَالَ ٱلَّذِينَ لَا يَرْجُونَ لِقَآءَنَا ٱئْتِ بِقُرْءَانٍ غَيْرِ هَـٰذَآ أَوْ بَدِّلْهُ ۚ قُلْ مَا يَكُونُ لِىٓ أَنْ أُبَدِّلَهُۥ مِن تِلْقَآئِ نَفْسِىٓ ۖ إِنْ أَتَّبِعُ إِلَّا مَا يُوحَىٰٓ إِلَىَّ ۖ إِنِّىٓ أَخَافُ إِنْ عَصَيْتُ رَبِّى عَذَابَ يَوْمٍ عَظِيمٍ
Transliteration wa-idhā tut'lā ʿalayhim āyātunā bayyinātin qāla alladhīna lā yarjūna liqāanā i'ti biqur'ānin ghayri hādhā aw baddil'hu qul mā yakūnu lī an ubaddilahu min til'qāi nafsī in attabiʿu illā mā yūḥā ilayya innī akhāfu in ʿaṣaytu rabbī ʿadhāba yawmin ʿaẓīmin
Yoruba Nígbà tí wọ́n bá ń ké àwọn āyah Wa tó yanjú fún wọn, àwọn tí kò retí ìpàdé Wa (ní ọ̀run) yóò máa wí pé: “Mú Ƙur’ān kan wá yàtọ̀ sí èyí tàbí kí o yí i padà.” Sọ pé: “Kò lẹ́tọ̀ọ́ fún mi láti yí i padà láti ọ̀dọ̀ ara mi. Èmi kò tẹ̀lé kiní kan àyàfi ohun tí Wọ́n fi ránṣẹ́ sí mi ní ìmísí. Dájúdájú èmi ń páyà ìyà Ọjọ́ ńlá tí mo bá fi lè yapa Olúwa mi.”
Verse 16
قُل لَّوْ شَآءَ ٱللَّهُ مَا تَلَوْتُهُۥ عَلَيْكُمْ وَلَآ أَدْرَىٰكُم بِهِۦ ۖ فَقَدْ لَبِثْتُ فِيكُمْ عُمُرًا مِّن قَبْلِهِۦٓ ۚ أَفَلَا تَعْقِلُونَ
Transliteration qul law shāa l-lahu mā talawtuhu ʿalaykum walā adrākum bihi faqad labith'tu fīkum ʿumuran min qablihi afalā taʿqilūna
Yoruba Sọ pé: “Tí ó bá jẹ́ pé Allāhu bá fẹ́ ni, èmi ìbá tí lè ké al-Ƙur’ān fún yín, àti pé Allāhu ìbá tí fi ìmọ̀ rẹ̀ mọ̀ yín. Mo kúkú ti lo àwọn ọdún kan láààrin yín ṣíwájú (ìsọ̀kalẹ̀) rẹ̀, ṣé ẹ ò ṣe làákàyè ni?”
Verse 17
فَمَنْ أَظْلَمُ مِمَّنِ ٱفْتَرَىٰ عَلَى ٱللَّهِ كَذِبًا أَوْ كَذَّبَ بِـَٔايَـٰتِهِۦٓ ۚ إِنَّهُۥ لَا يُفْلِحُ ٱلْمُجْرِمُونَ
Transliteration faman aẓlamu mimmani if'tarā ʿalā l-lahi kadhiban aw kadhaba biāyātihi innahu lā yuf'liḥu l-muj'rimūna
Yoruba Nítorí náà, ta ló ṣàbòsí ju ẹni tó dá àdápa irọ́ mọ́ Allāhu tàbí tó pe àwọn āyah Rẹ̀ nírọ́? Dájúdájú àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ kò níí jèrè.
Verse 18
وَيَعْبُدُونَ مِن دُونِ ٱللَّهِ مَا لَا يَضُرُّهُمْ وَلَا يَنفَعُهُمْ وَيَقُولُونَ هَـٰٓؤُلَآءِ شُفَعَـٰٓؤُنَا عِندَ ٱللَّهِ ۚ قُلْ أَتُنَبِّـُٔونَ ٱللَّهَ بِمَا لَا يَعْلَمُ فِى ٱلسَّمَـٰوَٰتِ وَلَا فِى ٱلْأَرْضِ ۚ سُبْحَـٰنَهُۥ وَتَعَـٰلَىٰ عَمَّا يُشْرِكُونَ
Transliteration wayaʿbudūna min dūni l-lahi mā lā yaḍurruhum walā yanfaʿuhum wayaqūlūna hāulāi shufaʿāunā ʿinda l-lahi qul atunabbiūna l-laha bimā lā yaʿlamu fī l-samāwāti walā fī l-arḍi sub'ḥānahu wataʿālā ʿammā yush'rikūna
Yoruba Wọ́n ń jọ́sìn fún ohun tí kò lè kó ìnira bá wọn, tí kò sì lè ṣe wọ́n ní àǹfààní lẹ́yìn Allāhu. Wọ́n sì ń wí pé: “Àwọn wọ̀nyí ni olùṣìpẹ̀ wa lọ́dọ̀ Allāhu.” Sọ pé: “Ṣé ẹ máa fún Allāhu ní ìró ohun tí kò mọ̀ nínú àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ ni?” Mímọ́ ni fún Un, Ó ga tayọ n̄ǹkan tí wọ́n ń fi ṣẹbọ sí I.
Verse 19
وَمَا كَانَ ٱلنَّاسُ إِلَّآ أُمَّةً وَٰحِدَةً فَٱخْتَلَفُوا۟ ۚ وَلَوْلَا كَلِمَةٌ سَبَقَتْ مِن رَّبِّكَ لَقُضِىَ بَيْنَهُمْ فِيمَا فِيهِ يَخْتَلِفُونَ
Transliteration wamā kāna l-nāsu illā ummatan wāḥidatan fa-ikh'talafū walawlā kalimatun sabaqat min rabbika laquḍiya baynahum fīmā fīhi yakhtalifūna
Yoruba Kí ni àwọn ènìyàn jẹ́ (ní ìpìlẹ̀) bí kò ṣe ìjọ ẹyọ kan (ìjọ ’Islām). Lẹ́yìn náà ni wọ́n yapa-ẹnu. Tí kò bá jẹ́ pé ọ̀rọ̀ kan tó ti ṣíwájú lọ́dọ̀ Olúwa rẹ, Àwa ìbá ti yanjú ohun tí wọ́n ń yapa-ẹnu lórí rẹ̀ láààrin ara wọn.
Verse 20
وَيَقُولُونَ لَوْلَآ أُنزِلَ عَلَيْهِ ءَايَةٌ مِّن رَّبِّهِۦ ۖ فَقُلْ إِنَّمَا ٱلْغَيْبُ لِلَّهِ فَٱنتَظِرُوٓا۟ إِنِّى مَعَكُم مِّنَ ٱلْمُنتَظِرِينَ
Transliteration wayaqūlūna lawlā unzila ʿalayhi āyatun min rabbihi faqul innamā l-ghaybu lillahi fa-intaẓirū innī maʿakum mina l-muntaẓirīna
Yoruba Wọ́n ń wí pé: “Kí ni kò jẹ́ kí àmì kan sọ̀kalẹ̀ fún un láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ̀?” Nítorí náà, sọ pé: “Ti Allāhu ni ìkọ̀kọ̀. Nítorí náà, ẹ máa retí. Dájúdájú èmi náà wà pẹ̀lú yín nínú àwọn olùretí.”
Verse 21
وَإِذَآ أَذَقْنَا ٱلنَّاسَ رَحْمَةً مِّنۢ بَعْدِ ضَرَّآءَ مَسَّتْهُمْ إِذَا لَهُم مَّكْرٌ فِىٓ ءَايَاتِنَا ۚ قُلِ ٱللَّهُ أَسْرَعُ مَكْرًا ۚ إِنَّ رُسُلَنَا يَكْتُبُونَ مَا تَمْكُرُونَ
Transliteration wa-idhā adhaqnā l-nāsa raḥmatan min baʿdi ḍarrāa massathum idhā lahum makrun fī āyātinā quli l-lahu asraʿu makran inna rusulanā yaktubūna mā tamkurūna
Yoruba Nígbà tí A bá fún àwọn ènìyàn ní ìdẹ̀ra kan tọ́wò lẹ́yìn tí ìnira ti fọwọ́ bà wọ́n, nígbà náà ni wọ́n yóò máa dète sí àwọn āyah Wa. Sọ pé: “Allāhu yára jùlọ níbi ète.Dájúdájú àwọn Òjíṣẹ́ Wa ń ṣe àkọsílẹ̀ ohun tí ẹ̀ ń dá ní ète.”
Verse 22
هُوَ ٱلَّذِى يُسَيِّرُكُمْ فِى ٱلْبَرِّ وَٱلْبَحْرِ ۖ حَتَّىٰٓ إِذَا كُنتُمْ فِى ٱلْفُلْكِ وَجَرَيْنَ بِهِم بِرِيحٍ طَيِّبَةٍ وَفَرِحُوا۟ بِهَا جَآءَتْهَا رِيحٌ عَاصِفٌ وَجَآءَهُمُ ٱلْمَوْجُ مِن كُلِّ مَكَانٍ وَظَنُّوٓا۟ أَنَّهُمْ أُحِيطَ بِهِمْ ۙ دَعَوُا۟ ٱللَّهَ مُخْلِصِينَ لَهُ ٱلدِّينَ لَئِنْ أَنجَيْتَنَا مِنْ هَـٰذِهِۦ لَنَكُونَنَّ مِنَ ٱلشَّـٰكِرِينَ
Transliteration huwa alladhī yusayyirukum fī l-bari wal-baḥri ḥattā idhā kuntum fī l-ful'ki wajarayna bihim birīḥin ṭayyibatin wafariḥū bihā jāathā rīḥun ʿāṣifun wajāahumu l-mawju min kulli makānin waẓannū annahum uḥīṭa bihim daʿawū l-laha mukh'liṣīna lahu l-dīna la-in anjaytanā min hādhihi lanakūnanna mina l-shākirīna
Yoruba (Allāhu) Òun ni Ẹni tí Ó mu yín rìn lórí ilẹ̀ àti ní ojú omi, títí di ìgbà tí ẹ bá wà nínú ọkọ̀ ojú-omi, tí ó ń gbé wọn lọ pẹ̀lú atẹ́gùn tó dára, inú wọn yó sì máa dùn sí i. (Àmọ́) atẹ́gùn líle kọ lù ú, ìgbì omi dé bá wọn ní gbogbo àyè, wọ́n sì mọ̀ pé dájúdájú wọ́n ti fi (àdánwò) yí àwọn po, wọ́n máa pe Allāhu lẹ́ni tí yóò máa fi àfọ̀mọ́-ọkàn (àníyàn mímọ́) ṣe ẹ̀sìn fún Un(wọ́n sì máa sọ pé): “Dájúdájú tí O bá fi lè gbà wá là níbi èyí, dájúdájú a máa wà nínú àwọn olùdúpẹ́.”
Verse 23
فَلَمَّآ أَنجَىٰهُمْ إِذَا هُمْ يَبْغُونَ فِى ٱلْأَرْضِ بِغَيْرِ ٱلْحَقِّ ۗ يَـٰٓأَيُّهَا ٱلنَّاسُ إِنَّمَا بَغْيُكُمْ عَلَىٰٓ أَنفُسِكُم ۖ مَّتَـٰعَ ٱلْحَيَوٰةِ ٱلدُّنْيَا ۖ ثُمَّ إِلَيْنَا مَرْجِعُكُمْ فَنُنَبِّئُكُم بِمَا كُنتُمْ تَعْمَلُونَ
Transliteration falammā anjāhum idhā hum yabghūna fī l-arḍi bighayri l-ḥaqi yāayyuhā l-nāsu innamā baghyukum ʿalā anfusikum matāʿa l-ḥayati l-dun'yā thumma ilaynā marjiʿukum fanunabbi-ukum bimā kuntum taʿmalūna
Yoruba Ṣùgbọ́n nígbà tí Ó gbà wọ́n là tán ìgbà náà ni wọ́n tún ń ṣe ìbàjẹ́ kiri lórí ilẹ̀ láì lẹ́tọ̀ọ́. Ẹ̀yin ènìyàn, dájúdájú ìbàjẹ́ yín ń bẹ lórí yín. (Ìbàjẹ́ yín sì jẹ́) ìgbádùn ìṣẹ̀mí ayé. Lẹ́yìn náà, ọ̀dọ̀ Wa ni ibùpadàsí yín. A sì máa fún yín ní ìró ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.
Verse 24
إِنَّمَا مَثَلُ ٱلْحَيَوٰةِ ٱلدُّنْيَا كَمَآءٍ أَنزَلْنَـٰهُ مِنَ ٱلسَّمَآءِ فَٱخْتَلَطَ بِهِۦ نَبَاتُ ٱلْأَرْضِ مِمَّا يَأْكُلُ ٱلنَّاسُ وَٱلْأَنْعَـٰمُ حَتَّىٰٓ إِذَآ أَخَذَتِ ٱلْأَرْضُ زُخْرُفَهَا وَٱزَّيَّنَتْ وَظَنَّ أَهْلُهَآ أَنَّهُمْ قَـٰدِرُونَ عَلَيْهَآ أَتَىٰهَآ أَمْرُنَا لَيْلًا أَوْ نَهَارًا فَجَعَلْنَـٰهَا حَصِيدًا كَأَن لَّمْ تَغْنَ بِٱلْأَمْسِ ۚ كَذَٰلِكَ نُفَصِّلُ ٱلْـَٔايَـٰتِ لِقَوْمٍ يَتَفَكَّرُونَ
Transliteration innamā mathalu l-ḥayati l-dun'yā kamāin anzalnāhu mina l-samāi fa-ikh'talaṭa bihi nabātu l-arḍi mimmā yakulu l-nāsu wal-anʿāmu ḥattā idhā akhadhati l-arḍu zukh'rufahā wa-izzayyanat waẓanna ahluhā annahum qādirūna ʿalayhā atāhā amrunā laylan aw nahāran fajaʿalnāhā ḥaṣīdan ka-an lam taghna bil-amsi kadhālika nufaṣṣilu l-āyāti liqawmin yatafakkarūna
Yoruba Àpèjúwe ìṣẹ̀mí ayé dà bí omi kan tí A sọ̀kalẹ̀ láti sánmọ̀, tí àwọn irúgbìn nínú ohun tí ènìyàn àti àwọn ẹran-ọ̀sìn ń jẹ sì gbà á sára, títí di ìgbà tí ilẹ̀ yóò fi lọ́ràá. Ó sì mú ọ̀ṣọ́ (ara) rẹ̀ jáde. Àwọn tó ni ín sì lérò pé àwọn ni alágbára lórí rẹ̀, (nígbà náà ni) àṣẹ Wa dé bá a ní òru tàbí ní ọ̀sán. A sì sọ ọ́ di oko tí wọ́n fà tu dànù bí ẹni pé kò sí níbẹ̀ rárá rí ní àná. Báyẹn ni A ṣe ń ṣàlàyé àwọn āyah fún ìjọ aláròjinlẹ̀.
Verse 25
وَٱللَّهُ يَدْعُوٓا۟ إِلَىٰ دَارِ ٱلسَّلَـٰمِ وَيَهْدِى مَن يَشَآءُ إِلَىٰ صِرَٰطٍ مُّسْتَقِيمٍ
Transliteration wal-lahu yadʿū ilā dāri l-salāmi wayahdī man yashāu ilā ṣirāṭin mus'taqīmin
Yoruba Allāhu ń pèpè sí ilé Àlàáfíà. Ó sì ń tọ́ ẹni tí Ó bá fẹ́ sí ọ̀nà tààrà (’Islām).
Verse 26
۞ لِّلَّذِينَ أَحْسَنُوا۟ ٱلْحُسْنَىٰ وَزِيَادَةٌ ۖ وَلَا يَرْهَقُ وُجُوهَهُمْ قَتَرٌ وَلَا ذِلَّةٌ ۚ أُو۟لَـٰٓئِكَ أَصْحَـٰبُ ٱلْجَنَّةِ ۖ هُمْ فِيهَا خَـٰلِدُونَ
Transliteration lilladhīna aḥsanū l-ḥus'nā waziyādatun walā yarhaqu wujūhahum qatarun walā dhillatun ulāika aṣḥābu l-janati hum fīhā khālidūna
Yoruba Rere àti àlékún (oore) wà fún àwọn tó ṣe rere. Eruku tàbí ìyẹpẹrẹ kan kò níí bò wọ́n lójú mọ́lẹ̀. Àwọn wọ̀nyẹn ni èrò inú Ọgbà Ìdẹ̀ra. Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀.
Verse 27
وَٱلَّذِينَ كَسَبُوا۟ ٱلسَّيِّـَٔاتِ جَزَآءُ سَيِّئَةٍۭ بِمِثْلِهَا وَتَرْهَقُهُمْ ذِلَّةٌ ۖ مَّا لَهُم مِّنَ ٱللَّهِ مِنْ عَاصِمٍ ۖ كَأَنَّمَآ أُغْشِيَتْ وُجُوهُهُمْ قِطَعًا مِّنَ ٱلَّيْلِ مُظْلِمًا ۚ أُو۟لَـٰٓئِكَ أَصْحَـٰبُ ٱلنَّارِ ۖ هُمْ فِيهَا خَـٰلِدُونَ
Transliteration wa-alladhīna kasabū l-sayiāti jazāu sayyi-atin bimith'lihā watarhaquhum dhillatun mā lahum mina l-lahi min ʿāṣimin ka-annamā ugh'shiyat wujūhuhum qiṭaʿan mina al-layli muẓ'liman ulāika aṣḥābu l-nāri hum fīhā khālidūna
Yoruba Àwọn tó sì ṣ’iṣẹ́ aburú, ẹ̀san aburú bí irú rẹ̀ (ni ẹ̀san wọn). Ìyẹpẹrẹ sì máa bò wọ́n mọ́lẹ̀. Kò sí aláàbò kan fún wọn lọ́dọ̀ Allāhu. (Wọ́n máa dà bí) ẹni pé wọ́n fi apá kan òru tó ṣókùnkùn bò wọ́n lójú pa. Àwọn wọ̀nyẹn ni èrò inú Iná. Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀.
Verse 28
وَيَوْمَ نَحْشُرُهُمْ جَمِيعًا ثُمَّ نَقُولُ لِلَّذِينَ أَشْرَكُوا۟ مَكَانَكُمْ أَنتُمْ وَشُرَكَآؤُكُمْ ۚ فَزَيَّلْنَا بَيْنَهُمْ ۖ وَقَالَ شُرَكَآؤُهُم مَّا كُنتُمْ إِيَّانَا تَعْبُدُونَ
Transliteration wayawma naḥshuruhum jamīʿan thumma naqūlu lilladhīna ashrakū makānakum antum washurakāukum fazayyalnā baynahum waqāla shurakāuhum mā kuntum iyyānā taʿbudūna
Yoruba Àti pé (rántí) Ọjọ́ tí A óò kó gbogbo wọn jọ, lẹ́yìn náà A óò sọ fún àwọn tó bá Allāhu wá akẹgbẹ́ pé: “Ẹ dúró pa sí àyè yín, ẹ̀yin àti àwọn òrìṣà yín.” Nítorí náà, A yà wọ́n sí ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Àwọn òrìṣà wọn sì wí pé: “Àwa kọ́ ni ẹ̀ ń jọ́sìn fún.”
Verse 29
فَكَفَىٰ بِٱللَّهِ شَهِيدًۢا بَيْنَنَا وَبَيْنَكُمْ إِن كُنَّا عَنْ عِبَادَتِكُمْ لَغَـٰفِلِينَ
Transliteration fakafā bil-lahi shahīdan baynanā wabaynakum in kunnā ʿan ʿibādatikum laghāfilīna
Yoruba Nítorí náà, Allāhu tó ní Ẹlẹ́rìí láààrin àwa àti ẹ̀yin pé àwa jẹ́ aláìmọ̀ nípa ìjọ́sìn yín (tí ẹ̀ ṣe fún wa).”
Verse 30
هُنَالِكَ تَبْلُوا۟ كُلُّ نَفْسٍ مَّآ أَسْلَفَتْ ۚ وَرُدُّوٓا۟ إِلَى ٱللَّهِ مَوْلَىٰهُمُ ٱلْحَقِّ ۖ وَضَلَّ عَنْهُم مَّا كَانُوا۟ يَفْتَرُونَ
Transliteration hunālika tablū kullu nafsin mā aslafat waruddū ilā l-lahi mawlāhumu l-ḥaqi waḍalla ʿanhum mā kānū yaftarūna
Yoruba Níbẹ̀ yẹn, ẹ̀mí kọ̀ọ̀kan máa dá ohun tó ṣe síwájú mọ̀. Wọn yó sì da wọ́n padà sọ́dọ̀ Allāhu Olúwa wọn Òdodo. Ohun tí wọ́n ń dá ní àdápa irọ́ sì di òfo mọ́ wọn lọ́wọ́.1
Verse 31
قُلْ مَن يَرْزُقُكُم مِّنَ ٱلسَّمَآءِ وَٱلْأَرْضِ أَمَّن يَمْلِكُ ٱلسَّمْعَ وَٱلْأَبْصَـٰرَ وَمَن يُخْرِجُ ٱلْحَىَّ مِنَ ٱلْمَيِّتِ وَيُخْرِجُ ٱلْمَيِّتَ مِنَ ٱلْحَىِّ وَمَن يُدَبِّرُ ٱلْأَمْرَ ۚ فَسَيَقُولُونَ ٱللَّهُ ۚ فَقُلْ أَفَلَا تَتَّقُونَ
Transliteration qul man yarzuqukum mina l-samāi wal-arḍi amman yamliku l-samʿa wal-abṣāra waman yukh'riju l-ḥaya mina l-mayiti wayukh'riju l-mayita mina l-ḥayi waman yudabbiru l-amra fasayaqūlūna l-lahu faqul afalā tattaqūna
Yoruba Sọ pé: “Ta ni Ó ń pèsè fún yín láti inú sánmọ̀ àti ilẹ̀? Ta ni Ó ní ìkápá lórí ìgbọ́rọ̀ àti ìríran? Ta ni Ó ń mú alààyè jáde láti ara òkú, tí Ó tún ń mú òkú jáde láti ara alààyè? Ta sì ni Ó ń ṣe ètò ọ̀rọ̀ (ẹ̀dá)?” Wọn yóò wí pé: “Allāhu” Nígbà náà, sọ pé: “Ṣé ẹ ò níí bẹ̀rù (Rẹ̀) ni?”
Verse 32
فَذَٰلِكُمُ ٱللَّهُ رَبُّكُمُ ٱلْحَقُّ ۖ فَمَاذَا بَعْدَ ٱلْحَقِّ إِلَّا ٱلضَّلَـٰلُ ۖ فَأَنَّىٰ تُصْرَفُونَ
Transliteration fadhālikumu l-lahu rabbukumu l-ḥaqu famādhā baʿda l-ḥaqi illā l-ḍalālu fa-annā tuṣ'rafūna
Yoruba Ìyẹn ni Allāhu Olúwa yín Òdodo. Kí sì ni ó ń bẹ lẹ́yìn Òdodo bí kò ṣe ìṣìnà? Nítorí náà, báwo ni wọ́n ṣe ń ṣẹ́rí yín kúrò níbi òdodo?
Verse 33
كَذَٰلِكَ حَقَّتْ كَلِمَتُ رَبِّكَ عَلَى ٱلَّذِينَ فَسَقُوٓا۟ أَنَّهُمْ لَا يُؤْمِنُونَ
Transliteration kadhālika ḥaqqat kalimatu rabbika ʿalā alladhīna fasaqū annahum lā yu'minūna
Yoruba Báyẹn ni ọ̀rọ̀ Olúwa rẹ ṣe wá sí ìmúṣẹ lórí àwọn tó ṣèbàjẹ́ pé dájúdájú wọn kò níí gbàgbọ́.
Verse 34
قُلْ هَلْ مِن شُرَكَآئِكُم مَّن يَبْدَؤُا۟ ٱلْخَلْقَ ثُمَّ يُعِيدُهُۥ ۚ قُلِ ٱللَّهُ يَبْدَؤُا۟ ٱلْخَلْقَ ثُمَّ يُعِيدُهُۥ ۖ فَأَنَّىٰ تُؤْفَكُونَ
Transliteration qul hal min shurakāikum man yabda-u l-khalqa thumma yuʿīduhu quli l-lahu yabda-u l-khalqa thumma yuʿīduhu fa-annā tu'fakūna
Yoruba Sọ pé: “Ǹjẹ́ ó wà nínú àwọn òrìṣà yín ẹni tí ó lè pilẹ̀ dídá ẹ̀dá, lẹ́yìn náà, tí ó máa dá a padà (sí ìpìlẹ̀ rẹ̀ lẹ́yìn ikú)?” Sọ pé: “Allāhu l’Ó ń pilẹ̀ dídá ẹ̀dá. Lẹ́yìn náà, Ó máa dá a padà (sí ìpìlẹ̀ rẹ̀ lẹ́yìn ikú). Nítorí náà, báwo ni wọ́n ṣe ń ṣẹ́rí yín kúrò níbi òdodo?
Verse 35
قُلْ هَلْ مِن شُرَكَآئِكُم مَّن يَهْدِىٓ إِلَى ٱلْحَقِّ ۚ قُلِ ٱللَّهُ يَهْدِى لِلْحَقِّ ۗ أَفَمَن يَهْدِىٓ إِلَى ٱلْحَقِّ أَحَقُّ أَن يُتَّبَعَ أَمَّن لَّا يَهِدِّىٓ إِلَّآ أَن يُهْدَىٰ ۖ فَمَا لَكُمْ كَيْفَ تَحْكُمُونَ
Transliteration qul hal min shurakāikum man yahdī ilā l-ḥaqi quli l-lahu yahdī lil'ḥaqqi afaman yahdī ilā l-ḥaqi aḥaqqu an yuttabaʿa amman lā yahiddī illā an yuh'dā famā lakum kayfa taḥkumūna
Yoruba Sọ pé: “Ǹjẹ́ ó wà nínú àwọn òrìṣà yín ẹni tó ń fini mọ̀nà síbi òdodo?” Sọ pé: “Allāhu l’Ó ń fini mọ̀nà síbi òdodo. Nígbà náà, ṣé Ẹni t’Ó ń fini mọ̀nà síbi òdodo ló lẹ́tọ̀ọ́ jùlọ sí pé kí wọ́n máa tẹ̀lé ni tàbí ẹni tí kò lè dá ọ̀nà mọ̀ fúnra rẹ̀ àfi tí A bá fi mọ̀nà?” Nítorí náà, kí ló ń ṣe yín tí ẹ fi ń dájọ́ báyìí?
Verse 36
وَمَا يَتَّبِعُ أَكْثَرُهُمْ إِلَّا ظَنًّا ۚ إِنَّ ٱلظَّنَّ لَا يُغْنِى مِنَ ٱلْحَقِّ شَيْـًٔا ۚ إِنَّ ٱللَّهَ عَلِيمٌۢ بِمَا يَفْعَلُونَ
Transliteration wamā yattabiʿu aktharuhum illā ẓannan inna l-ẓana lā yugh'nī mina l-ḥaqi shayan inna l-laha ʿalīmun bimā yafʿalūna
Yoruba Ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn kò sì rí kiní kan tẹ̀lé bí kò ṣe àròsọ. Dájúdájú àbá dídá kò sì lè rọrọ̀ kiní kan níwájú òdodo. Dájúdájú Allāhu ni Onímọ̀ nípa ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́.
Verse 37
وَمَا كَانَ هَـٰذَا ٱلْقُرْءَانُ أَن يُفْتَرَىٰ مِن دُونِ ٱللَّهِ وَلَـٰكِن تَصْدِيقَ ٱلَّذِى بَيْنَ يَدَيْهِ وَتَفْصِيلَ ٱلْكِتَـٰبِ لَا رَيْبَ فِيهِ مِن رَّبِّ ٱلْعَـٰلَمِينَ
Transliteration wamā kāna hādhā l-qur'ānu an yuf'tarā min dūni l-lahi walākin taṣdīqa alladhī bayna yadayhi watafṣīla l-kitābi lā rayba fīhi min rabbi l-ʿālamīna
Yoruba Al-Ƙur’ān yìí kì í ṣe n̄ǹkan tí ó ṣe é dáhun (láti ọ̀dọ̀ ẹlòmíìràn) lẹ́yìn Allāhu, ṣùgbọ́n ó ń jẹ́rìí sí èyí tó jẹ́ òdodo nínú èyí tó ṣíwájú rẹ̀, ó ń ṣe àlàyé (àwọn) Tírà náà. Kò sí iyèméjì nínú rẹ̀. (Ó wá) láti ọ̀dọ̀ Olúwa gbogbo ẹ̀dá.
Verse 38
أَمْ يَقُولُونَ ٱفْتَرَىٰهُ ۖ قُلْ فَأْتُوا۟ بِسُورَةٍ مِّثْلِهِۦ وَٱدْعُوا۟ مَنِ ٱسْتَطَعْتُم مِّن دُونِ ٱللَّهِ إِن كُنتُمْ صَـٰدِقِينَ
Transliteration am yaqūlūna if'tarāhu qul fatū bisūratin mith'lihi wa-id'ʿū mani is'taṭaʿtum min dūni l-lahi in kuntum ṣādiqīna
Yoruba Tàbí wọ́n ń wí pé: “Ó hun ún ni? Sọ pé: “Ẹ mú sūrah kan bí irú rẹ̀ wá. Kí ẹ sì pe ẹnikẹ́ni tí ẹ bá lè pè lẹ́yìn Allāhu, tí ẹ bá jẹ́ olódodo.”
Verse 39
بَلْ كَذَّبُوا۟ بِمَا لَمْ يُحِيطُوا۟ بِعِلْمِهِۦ وَلَمَّا يَأْتِهِمْ تَأْوِيلُهُۥ ۚ كَذَٰلِكَ كَذَّبَ ٱلَّذِينَ مِن قَبْلِهِمْ ۖ فَٱنظُرْ كَيْفَ كَانَ عَـٰقِبَةُ ٱلظَّـٰلِمِينَ
Transliteration bal kadhabū bimā lam yuḥīṭū biʿil'mihi walammā yatihim tawīluhu kadhālika kadhaba alladhīna min qablihim fa-unẓur kayfa kāna ʿāqibatu l-ẓālimīna
Yoruba Kò rí bẹ́è, wọ́n pe ohun tí wọn kò ní ìmọ̀ rẹ̀ nírọ́ ni. Àti pé ìmúṣẹ ọ̀rọ̀ Rẹ̀ kò tí ì dé bá wọn (ni wọ́n fi pè é nírọ́). Báyẹn ni àwọn tó ṣíwájú wọn ṣe pe (ọ̀rọ̀ Allāhu) nírọ́. Nítorí náà, wo bí àtubọ̀tán àwọn alábòsí ṣe rí.
Verse 40
وَمِنْهُم مَّن يُؤْمِنُ بِهِۦ وَمِنْهُم مَّن لَّا يُؤْمِنُ بِهِۦ ۚ وَرَبُّكَ أَعْلَمُ بِٱلْمُفْسِدِينَ
Transliteration wamin'hum man yu'minu bihi wamin'hum man lā yu'minu bihi warabbuka aʿlamu bil-muf'sidīna
Yoruba Ó sì ń bẹ nínú wọn ẹni tó gbà á gbọ́ ní òdodo. Ó tún ń bẹ́ nínú wọn ẹni tí kò gbà á gbọ́. Olúwa rẹ sì ni Onímọ̀-jùlọ nípa àwọn òbìlẹ̀jẹ́.
Verse 41
وَإِن كَذَّبُوكَ فَقُل لِّى عَمَلِى وَلَكُمْ عَمَلُكُمْ ۖ أَنتُم بَرِيٓـُٔونَ مِمَّآ أَعْمَلُ وَأَنَا۠ بَرِىٓءٌ مِّمَّا تَعْمَلُونَ
Transliteration wa-in kadhabūka faqul lī ʿamalī walakum ʿamalukum antum barīūna mimmā aʿmalu wa-anā barīon mimmā taʿmalūna
Yoruba Tí wọ́n bá pè ọ́ ní òpùrọ́, sọ pé: “Tèmi ni iṣẹ́ mi. Tiyín ni iṣẹ́ yín. Ẹ̀yin yọwọ́ yọsẹ̀ nínú ohun tí mò ń ṣe níṣẹ́. Èmi náà sì yọwọ́ yọsẹ̀ nínú ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.”
Verse 42
وَمِنْهُم مَّن يَسْتَمِعُونَ إِلَيْكَ ۚ أَفَأَنتَ تُسْمِعُ ٱلصُّمَّ وَلَوْ كَانُوا۟ لَا يَعْقِلُونَ
Transliteration wamin'hum man yastamiʿūna ilayka afa-anta tus'miʿu l-ṣuma walaw kānū lā yaʿqilūna
Yoruba Ó sì wà nínú wọn, àwọn tó ń tẹ́tí sí ọ. Ṣé ìwọ lo máa mú adití gbọ́rọ̀ ni, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn kì í ṣe làákàyè?1
Verse 43
وَمِنْهُم مَّن يَنظُرُ إِلَيْكَ ۚ أَفَأَنتَ تَهْدِى ٱلْعُمْىَ وَلَوْ كَانُوا۟ لَا يُبْصِرُونَ
Transliteration wamin'hum man yanẓuru ilayka afa-anta tahdī l-ʿum'ya walaw kānū lā yub'ṣirūna
Yoruba Ó tún ń bẹ nínú wọn ẹni tó ń wò ọ́. Ṣé ìwọ lo máa fi afọ́jú mọ̀nà ni, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn kì í ríran?
Verse 44
إِنَّ ٱللَّهَ لَا يَظْلِمُ ٱلنَّاسَ شَيْـًٔا وَلَـٰكِنَّ ٱلنَّاسَ أَنفُسَهُمْ يَظْلِمُونَ
Transliteration inna l-laha lā yaẓlimu l-nāsa shayan walākinna l-nāsa anfusahum yaẓlimūna
Yoruba Dájúdájú Allāhu kò níí fí kiní kan ṣàbòsí sí ènìyàn. Ṣùgbọ́n ènìyàn ń ṣàbòsí sí ẹ̀mí ara wọn.
Verse 45
وَيَوْمَ يَحْشُرُهُمْ كَأَن لَّمْ يَلْبَثُوٓا۟ إِلَّا سَاعَةً مِّنَ ٱلنَّهَارِ يَتَعَارَفُونَ بَيْنَهُمْ ۚ قَدْ خَسِرَ ٱلَّذِينَ كَذَّبُوا۟ بِلِقَآءِ ٱللَّهِ وَمَا كَانُوا۟ مُهْتَدِينَ
Transliteration wayawma yaḥshuruhum ka-an lam yalbathū illā sāʿatan mina l-nahāri yataʿārafūna baynahum qad khasira alladhīna kadhabū biliqāi l-lahi wamā kānū muh'tadīna
Yoruba Àti pé (rántí) Ọjọ́ tí (Allāhu) yóò kó wọn jọ àfi bí ẹni pé wọn kò gbé ilé ayé ju àkókò kan nínú ọ̀sán. Wọn yó sì dára wọn mọ̀. Dájúdájú àwọn tó pe ìpàdé Allāhu nírọ́ ti ṣòfò; wọn kò sì jẹ́ olùmọ̀nà.
Verse 46
وَإِمَّا نُرِيَنَّكَ بَعْضَ ٱلَّذِى نَعِدُهُمْ أَوْ نَتَوَفَّيَنَّكَ فَإِلَيْنَا مَرْجِعُهُمْ ثُمَّ ٱللَّهُ شَهِيدٌ عَلَىٰ مَا يَفْعَلُونَ
Transliteration wa-immā nuriyannaka baʿḍa alladhī naʿiduhum aw natawaffayannaka fa-ilaynā marjiʿuhum thumma l-lahu shahīdun ʿalā mā yafʿalūna
Yoruba Ó ṣeé ṣe kí A fi apá kan èyí tí A ṣe ní ìlérí fún wọn hàn ọ́ tàbí kí A ti gba ẹ̀mí rẹ (ṣíwájú àsìkò náà), ọ̀dọ̀ Wa kúkú ni ibùpadàsí wọn. Lẹ́yìn náà, Allāhu ni Arínú-róde ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́.
Verse 47
وَلِكُلِّ أُمَّةٍ رَّسُولٌ ۖ فَإِذَا جَآءَ رَسُولُهُمْ قُضِىَ بَيْنَهُم بِٱلْقِسْطِ وَهُمْ لَا يُظْلَمُونَ
Transliteration walikulli ummatin rasūlun fa-idhā jāa rasūluhum quḍiya baynahum bil-qis'ṭi wahum lā yuẓ'lamūna
Yoruba Òjíṣẹ́ ti wà fún ìjọ kọ̀ọ̀kan.Nítorí náà, nígbà tí Òjíṣẹ́ wọn bá dé, A óò ṣèdájọ́ láààrin wọn pẹ̀lú déédé; A ò sì níí ṣàbòsí sí wọn.
Verse 48
وَيَقُولُونَ مَتَىٰ هَـٰذَا ٱلْوَعْدُ إِن كُنتُمْ صَـٰدِقِينَ
Transliteration wayaqūlūna matā hādhā l-waʿdu in kuntum ṣādiqīna
Yoruba Wọ́n ń wí pé: “Ìgbà wo ni àdéhùn yìí yóò ṣẹ tí ẹ bá jẹ́ olódodo?”
Verse 49
قُل لَّآ أَمْلِكُ لِنَفْسِى ضَرًّا وَلَا نَفْعًا إِلَّا مَا شَآءَ ٱللَّهُ ۗ لِكُلِّ أُمَّةٍ أَجَلٌ ۚ إِذَا جَآءَ أَجَلُهُمْ فَلَا يَسْتَـْٔخِرُونَ سَاعَةً ۖ وَلَا يَسْتَقْدِمُونَ
Transliteration qul lā amliku linafsī ḍarran walā nafʿan illā mā shāa l-lahu likulli ummatin ajalun idhā jāa ajaluhum falā yastakhirūna sāʿatan walā yastaqdimūna
Yoruba Sọ pé: “Èmi kò ní ìkápá ìnira tàbí oore kan fún ẹ̀mí ara mi àfi ohun tí Allāhu bá fẹ́. Gbèdéke àkókò ti wà fún ìjọ kọ̀ọ̀kan. Nígbà tí àkókò wọn bá dé, wọn kò níí lè sún un ṣíwájú di àkókò kan, wọn kò sì níí lè fà á sẹ́yìn.”1
Verse 50
قُلْ أَرَءَيْتُمْ إِنْ أَتَىٰكُمْ عَذَابُهُۥ بَيَـٰتًا أَوْ نَهَارًا مَّاذَا يَسْتَعْجِلُ مِنْهُ ٱلْمُجْرِمُونَ
Transliteration qul ara-aytum in atākum ʿadhābuhu bayātan aw nahāran mādhā yastaʿjilu min'hu l-muj'rimūna
Yoruba Sọ pé: “Ẹ sọ fún mi, tí ìyà Rẹ̀ bá dé ba yín ní òru tàbí ní ọ̀sán? Èwo nínú rẹ̀ ni àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ń wá pẹ̀lú ìkánjú?”
Verse 51
أَثُمَّ إِذَا مَا وَقَعَ ءَامَنتُم بِهِۦٓ ۚ ءَآلْـَٔـٰنَ وَقَدْ كُنتُم بِهِۦ تَسْتَعْجِلُونَ
Transliteration athumma idhā mā waqaʿa āmantum bihi āl'āna waqad kuntum bihi tastaʿjilūna
Yoruba Ṣé lẹ́yìn ìgbà tí ó bá ṣẹlẹ̀ tán ni ẹ máa gbà á gbọ́? Ṣé nísinsìn yìí (ni ẹ óò gbà á gbọ́), tí ẹ sì kúkú ti ń wá a pẹ̀lú ìkánjú?
Verse 52
ثُمَّ قِيلَ لِلَّذِينَ ظَلَمُوا۟ ذُوقُوا۟ عَذَابَ ٱلْخُلْدِ هَلْ تُجْزَوْنَ إِلَّا بِمَا كُنتُمْ تَكْسِبُونَ
Transliteration thumma qīla lilladhīna ẓalamū dhūqū ʿadhāba l-khul'di hal tuj'zawna illā bimā kuntum taksibūna
Yoruba Lẹ́yìn náà, A óò sọ fún àwọn tó ṣàbòsí pé: “Ẹ tọ́ ìyà gbére wò.” Ṣé A óò san yín ní ẹ̀san kan bí kò ṣe ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́?
Verse 53
۞ وَيَسْتَنۢبِـُٔونَكَ أَحَقٌّ هُوَ ۖ قُلْ إِى وَرَبِّىٓ إِنَّهُۥ لَحَقٌّ ۖ وَمَآ أَنتُم بِمُعْجِزِينَ
Transliteration wayastanbiūnaka aḥaqqun huwa qul ī warabbī innahu laḥaqqun wamā antum bimuʿ'jizīna
Yoruba Wọ́n sì ń bèèrè fún ìró rẹ̀ lọ́dọ̀ rẹ̀ pé, “ṣé òdodo ni?” Sọ pé: “Bẹ́ẹ̀ ni. Mo fi Olúwa mi búra. Dájúdájú òdodo ni. Ẹ̀yin kò sì níí mórí bọ́.”
Verse 54
وَلَوْ أَنَّ لِكُلِّ نَفْسٍ ظَلَمَتْ مَا فِى ٱلْأَرْضِ لَٱفْتَدَتْ بِهِۦ ۗ وَأَسَرُّوا۟ ٱلنَّدَامَةَ لَمَّا رَأَوُا۟ ٱلْعَذَابَ ۖ وَقُضِىَ بَيْنَهُم بِٱلْقِسْطِ ۚ وَهُمْ لَا يُظْلَمُونَ
Transliteration walaw anna likulli nafsin ẓalamat mā fī l-arḍi la-if'tadat bihi wa-asarrū l-nadāmata lammā ra-awū l-ʿadhāba waquḍiya baynahum bil-qis'ṭi wahum lā yuẓ'lamūna
Yoruba Àti pé tí ó bá jẹ́ pé gbogbo n̄ǹkan tí ń bẹ lórí ilẹ̀ jẹ́ ti ẹ̀mí kọ̀ọ̀kan tó ṣàbòsí, ìbá fi ṣèràpadà (fún ẹ̀mí ara rẹ̀ níbi ìyà). Wọn yóò fi igbe àbámọ̀ pamọ́ nígbà tí wọ́n bá rí Ìyà. A ó ṣe ìdájọ́ láààrin wọn pẹ̀lú déédé; Wọn kò sì níí ṣàbòsí sí wọn.
Verse 55
أَلَآ إِنَّ لِلَّهِ مَا فِى ٱلسَّمَـٰوَٰتِ وَٱلْأَرْضِ ۗ أَلَآ إِنَّ وَعْدَ ٱللَّهِ حَقٌّ وَلَـٰكِنَّ أَكْثَرَهُمْ لَا يَعْلَمُونَ
Transliteration alā inna lillahi mā fī l-samāwāti wal-arḍi alā inna waʿda l-lahi ḥaqqun walākinna aktharahum lā yaʿlamūna
Yoruba Gbọ́, dájúdájú ti Allāhu ni ohunkóhun tó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Gbọ́! Dájúdájú àdéhùn Allāhu ni òdodo, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn kò nímọ̀.
Verse 56
هُوَ يُحْىِۦ وَيُمِيتُ وَإِلَيْهِ تُرْجَعُونَ
Transliteration huwa yuḥ'yī wayumītu wa-ilayhi tur'jaʿūna
Yoruba Ó ń sọ ẹ̀dá di alààyè. Ó sì ń sọ ẹ̀dá di òkú. Ọ̀dọ̀ Rẹ̀ sì ni wọn yóò da yín padà sí.
Verse 57
يَـٰٓأَيُّهَا ٱلنَّاسُ قَدْ جَآءَتْكُم مَّوْعِظَةٌ مِّن رَّبِّكُمْ وَشِفَآءٌ لِّمَا فِى ٱلصُّدُورِ وَهُدًى وَرَحْمَةٌ لِّلْمُؤْمِنِينَ
Transliteration yāayyuhā l-nāsu qad jāatkum mawʿiẓatun min rabbikum washifāon limā fī l-ṣudūri wahudan waraḥmatun lil'mu'minīna
Yoruba Èyin ènìyàn, ìṣítí kan láti ọ̀dọ̀ Olúwa yín ti dé ba yín. Ìwòsàn ni fún n̄ǹkan tó wà nínú àwọn igbá-àyà ẹ̀dá. Ìmọ̀nà àti ìkẹ́ ni fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo.
Verse 58
قُلْ بِفَضْلِ ٱللَّهِ وَبِرَحْمَتِهِۦ فَبِذَٰلِكَ فَلْيَفْرَحُوا۟ هُوَ خَيْرٌ مِّمَّا يَجْمَعُونَ
Transliteration qul bifaḍli l-lahi wabiraḥmatihi fabidhālika falyafraḥū huwa khayrun mimmā yajmaʿūna
Yoruba Sọ pé: “Pẹ̀lú oore àjùlọ Allāhu (ìyẹn, al-Ƙur’ān) àti àánú Rẹ̀ (ìyẹn, ’Islām), nítorí ìyẹn ni kí wọ́n máa fi dunnú; ó sì lóore ju ohun tí àwọn (aláìgbàgbọ́) ń kó jọ (nínú oore ayé).”
Verse 59
قُلْ أَرَءَيْتُم مَّآ أَنزَلَ ٱللَّهُ لَكُم مِّن رِّزْقٍ فَجَعَلْتُم مِّنْهُ حَرَامًا وَحَلَـٰلًا قُلْ ءَآللَّهُ أَذِنَ لَكُمْ ۖ أَمْ عَلَى ٱللَّهِ تَفْتَرُونَ
Transliteration qul ara-aytum mā anzala l-lahu lakum min riz'qin fajaʿaltum min'hu ḥarāman waḥalālan qul āllahu adhina lakum am ʿalā l-lahi taftarūna
Yoruba Sọ pé: “Ẹ sọ fún mi nípa àwọn n̄ǹkan tí Allāhu sọ̀kalẹ̀ fún yín nínú arísìkí, tí ẹ̀yin fúnra yín ṣe àwọn kan ní èèwọ̀ àti ẹ̀tọ́.” Sọ pé, “Ṣé Allāhu l’Ó yọ̀ǹda fún yín (láti ṣe bẹ́ẹ̀ ni) tàbí ẹ̀ ń dá àdápa irọ́ mọ́ Allāhu?”
Verse 60
وَمَا ظَنُّ ٱلَّذِينَ يَفْتَرُونَ عَلَى ٱللَّهِ ٱلْكَذِبَ يَوْمَ ٱلْقِيَـٰمَةِ ۗ إِنَّ ٱللَّهَ لَذُو فَضْلٍ عَلَى ٱلنَّاسِ وَلَـٰكِنَّ أَكْثَرَهُمْ لَا يَشْكُرُونَ
Transliteration wamā ẓannu alladhīna yaftarūna ʿalā l-lahi l-kadhiba yawma l-qiyāmati inna l-laha ladhū faḍlin ʿalā l-nāsi walākinna aktharahum lā yashkurūna
Yoruba Kí ni èrò-ọkàn àwọn tó ń dá àdápa irọ́ mọ́ Allāhu ní Ọjọ́ Àjíǹde ná? Dájúdájú Allāhu ni Ọlọ́lá-jùlọ lórí àwọn ènìyàn, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn ni kì í dúpẹ́ (fún Un).
Verse 61
وَمَا تَكُونُ فِى شَأْنٍ وَمَا تَتْلُوا۟ مِنْهُ مِن قُرْءَانٍ وَلَا تَعْمَلُونَ مِنْ عَمَلٍ إِلَّا كُنَّا عَلَيْكُمْ شُهُودًا إِذْ تُفِيضُونَ فِيهِ ۚ وَمَا يَعْزُبُ عَن رَّبِّكَ مِن مِّثْقَالِ ذَرَّةٍ فِى ٱلْأَرْضِ وَلَا فِى ٱلسَّمَآءِ وَلَآ أَصْغَرَ مِن ذَٰلِكَ وَلَآ أَكْبَرَ إِلَّا فِى كِتَـٰبٍ مُّبِينٍ
Transliteration wamā takūnu fī shanin wamā tatlū min'hu min qur'ānin walā taʿmalūna min ʿamalin illā kunnā ʿalaykum shuhūdan idh tufīḍūna fīhi wamā yaʿzubu ʿan rabbika min mith'qāli dharratin fī l-arḍi walā fī l-samāi walā aṣghara min dhālika walā akbara illā fī kitābin mubīnin
Yoruba Ìwọ kò níí wà nínú ìṣe kan, ìwọ kò sì níí ké (āyah kan) nínú al-Ƙur’ān, ẹ̀yin kò sì níí ṣe iṣẹ́ kan àfi kí Àwa jẹ́ Ẹlẹ́rìí lórí yín nígbà tí ẹ bá bẹ̀rẹ̀ sí ṣe é. Kiní kan kò pamọ́ fún Olúwa rẹ; ohun tí ó mọ ní òdíwọ̀n ọmọ iná-igún nínú ilẹ̀ àti nínú sánmọ̀, èyí tí ó kéré sí ìyẹn àti èyí tí ó tóbi jù ú lọ àfi kí ó wà nínú àkọsílẹ̀ tó yanjú.
Verse 62
أَلَآ إِنَّ أَوْلِيَآءَ ٱللَّهِ لَا خَوْفٌ عَلَيْهِمْ وَلَا هُمْ يَحْزَنُونَ
Transliteration alā inna awliyāa l-lahi lā khawfun ʿalayhim walā hum yaḥzanūna
Yoruba Gbọ́, dájúdájú àwọn ọ̀rẹ́ Allāhu, kò níí sí ìbẹ̀rù (ìyà ọ̀run) fún wọn, wọn kò sì níí banújẹ́ (lórí oore ayé).1
Verse 63
ٱلَّذِينَ ءَامَنُوا۟ وَكَانُوا۟ يَتَّقُونَ
Transliteration alladhīna āmanū wakānū yattaqūna
Yoruba (Àwọn ni) àwọn tó gbàgbọ́ lódodo, wọ́n sì máa ń bẹ̀rù (Allāhu).
Verse 64
لَهُمُ ٱلْبُشْرَىٰ فِى ٱلْحَيَوٰةِ ٱلدُّنْيَا وَفِى ٱلْـَٔاخِرَةِ ۚ لَا تَبْدِيلَ لِكَلِمَـٰتِ ٱللَّهِ ۚ ذَٰلِكَ هُوَ ٱلْفَوْزُ ٱلْعَظِيمُ
Transliteration lahumu l-bush'rā fī l-ḥayati l-dun'yā wafī l-ākhirati lā tabdīla likalimāti l-lahi dhālika huwa l-fawzu l-ʿaẓīmu
Yoruba Ti wọn ni ìró ìdùnnú nínú ìṣẹ̀mí ayé (yìí) àti ní Ọjọ́ Ìkẹ́yìn. Kò sí ìyípadà kan fún àwọn ọ̀rọ̀ Allāhu.Ìyẹn, òhun ni èrèǹjẹ ńlá.
Verse 65
وَلَا يَحْزُنكَ قَوْلُهُمْ ۘ إِنَّ ٱلْعِزَّةَ لِلَّهِ جَمِيعًا ۚ هُوَ ٱلسَّمِيعُ ٱلْعَلِيمُ
Transliteration walā yaḥzunka qawluhum inna l-ʿizata lillahi jamīʿan huwa l-samīʿu l-ʿalīmu
Yoruba Má ṣe jẹ́ kí ọ̀rọ̀ (ẹnu) wọn bà ọ́ nínú jẹ́. Dájúdájú gbogbo agbára pátápátá ń jẹ́ ti Allāhu. Òun ni Olùgbọ́, Onímọ̀.
Verse 66
أَلَآ إِنَّ لِلَّهِ مَن فِى ٱلسَّمَـٰوَٰتِ وَمَن فِى ٱلْأَرْضِ ۗ وَمَا يَتَّبِعُ ٱلَّذِينَ يَدْعُونَ مِن دُونِ ٱللَّهِ شُرَكَآءَ ۚ إِن يَتَّبِعُونَ إِلَّا ٱلظَّنَّ وَإِنْ هُمْ إِلَّا يَخْرُصُونَ
Transliteration alā inna lillahi man fī l-samāwāti waman fī l-arḍi wamā yattabiʿu alladhīna yadʿūna min dūni l-lahi shurakāa in yattabiʿūna illā l-ẓana wa-in hum illā yakhruṣūna
Yoruba Gbọ́, dájúdájú ti Allāhu ni ẹnikẹ́ni tó ń bẹ nínú àwọn sánmọ̀ àti ẹnikẹ́ni tó ń bẹ lórí ilẹ̀. Àwọn tó ń pe àwọn òrìṣà lẹ́yìn Allāhu kò (rí) akẹgbẹ́ Allāhu tẹ̀lé (torí pé, kò sí akẹgbẹ́ fún Allāhu níbìkan kan) Wọn kò tẹ̀lé (kiní kan) bí kò ṣe àbá dídá.Wọn kò sì ṣe kiní kan bí kò ṣe pé wọ́n ń parọ́.
Verse 67
هُوَ ٱلَّذِى جَعَلَ لَكُمُ ٱلَّيْلَ لِتَسْكُنُوا۟ فِيهِ وَٱلنَّهَارَ مُبْصِرًا ۚ إِنَّ فِى ذَٰلِكَ لَـَٔايَـٰتٍ لِّقَوْمٍ يَسْمَعُونَ
Transliteration huwa alladhī jaʿala lakumu al-layla litaskunū fīhi wal-nahāra mub'ṣiran inna fī dhālika laāyātin liqawmin yasmaʿūna
Yoruba Òun ni Ẹni t’Ó ṣe òru fún yín nítorí kí ẹ lè sinmi nínú rẹ̀. (Ó ṣe) ọ̀sán ní (àsìkò) ìríran (láti rìn káàkiri). Dájúdájú àwọn àmì wà nínú ìyẹn fún ìjọ tó ń gbọ́rọ̀ (òdodo).
Verse 68
قَالُوا۟ ٱتَّخَذَ ٱللَّهُ وَلَدًا ۗ سُبْحَـٰنَهُۥ ۖ هُوَ ٱلْغَنِىُّ ۖ لَهُۥ مَا فِى ٱلسَّمَـٰوَٰتِ وَمَا فِى ٱلْأَرْضِ ۚ إِنْ عِندَكُم مِّن سُلْطَـٰنٍۭ بِهَـٰذَآ ۚ أَتَقُولُونَ عَلَى ٱللَّهِ مَا لَا تَعْلَمُونَ
Transliteration qālū ittakhadha l-lahu waladan sub'ḥānahu huwa l-ghaniyu lahu mā fī l-samāwāti wamā fī l-arḍi in ʿindakum min sul'ṭānin bihādhā ataqūlūna ʿalā l-lahi mā lā taʿlamūna
Yoruba Wọ́n wí pé: “Allāhu sọ ẹnì kan di ọmọ.” - Mímọ́ ni fún Un. Òun ní Ọlọ́rọ̀.TiRẹ̀ ni ohunkóhun tó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ohunkóhun tó wà nínú ilẹ̀. - Kò sí ẹ̀rí kan lọ́dọ̀ yín lórí èyí. Ṣé ẹ̀yin yóò máa ṣe àfitì ọ̀rọ̀ tí ẹ ò nímọ̀ rẹ̀ sọ́dọ̀ Allāhu ni?
Verse 69
قُلْ إِنَّ ٱلَّذِينَ يَفْتَرُونَ عَلَى ٱللَّهِ ٱلْكَذِبَ لَا يُفْلِحُونَ
Transliteration qul inna alladhīna yaftarūna ʿalā l-lahi l-kadhiba lā yuf'liḥūna
Yoruba Sọ pé: “Dájúdájú àwọn tó ń dá àdápa irọ́ mọ́ Allāhu, wọn kò níí jèrè.”
Verse 70
مَتَـٰعٌ فِى ٱلدُّنْيَا ثُمَّ إِلَيْنَا مَرْجِعُهُمْ ثُمَّ نُذِيقُهُمُ ٱلْعَذَابَ ٱلشَّدِيدَ بِمَا كَانُوا۟ يَكْفُرُونَ
Transliteration matāʿun fī l-dun'yā thumma ilaynā marjiʿuhum thumma nudhīquhumu l-ʿadhāba l-shadīda bimā kānū yakfurūna
Yoruba Ìgbádùn bín-íntín (lè wà fún wọn) nílé ayé. Lẹ́yìn náà, ọ̀dọ̀ Wa ni ibùpadàsí wọn. Lẹ́yìn náà, A óò fún wọn ní ìyà líle tọ́ wò nítorí pé wọ́n ń ṣàì gbàgbọ́.
Verse 71
۞ وَٱتْلُ عَلَيْهِمْ نَبَأَ نُوحٍ إِذْ قَالَ لِقَوْمِهِۦ يَـٰقَوْمِ إِن كَانَ كَبُرَ عَلَيْكُم مَّقَامِى وَتَذْكِيرِى بِـَٔايَـٰتِ ٱللَّهِ فَعَلَى ٱللَّهِ تَوَكَّلْتُ فَأَجْمِعُوٓا۟ أَمْرَكُمْ وَشُرَكَآءَكُمْ ثُمَّ لَا يَكُنْ أَمْرُكُمْ عَلَيْكُمْ غُمَّةً ثُمَّ ٱقْضُوٓا۟ إِلَىَّ وَلَا تُنظِرُونِ
Transliteration wa-ut'lu ʿalayhim naba-a nūḥin idh qāla liqawmihi yāqawmi in kāna kabura ʿalaykum maqāmī watadhkīrī biāyāti l-lahi faʿalā l-lahi tawakkaltu fa-ajmiʿū amrakum washurakāakum thumma lā yakun amrukum ʿalaykum ghummatan thumma iq'ḍū ilayya walā tunẓirūni
Yoruba Ka ìròyìn (Ànábì) Nūh fún wọn. Nígbà tí ó sọ fún ìjọ rẹ̀ pé: “Ẹ̀yin ènìyàn mi, tí ó bá jẹ́ pé ìdúró mi (pẹ̀lú yín) àti bí mo ṣe ń fi àwọn āyah Allāhu ṣe ìṣítí fún yín bá lágbára lára yín, nígbà náà Allāhu ni mo gbáralé. Nítorí náà, ẹ pa ìmọ̀ràn yín pọ̀, (kí ẹ sì ké pe) àwọn òrìṣà yín. Lẹ́yìn náà, kí ìpinnu ọ̀rọ̀ yín má ṣe wà ní bòńkẹ́lẹ́ láààrin yín. Lẹ́yìn náà, kí ẹ yanjú ọ̀rọ̀ mi. Kí ẹ sì má ṣe lọ́ mi lára mọ́.
Verse 72
فَإِن تَوَلَّيْتُمْ فَمَا سَأَلْتُكُم مِّنْ أَجْرٍ ۖ إِنْ أَجْرِىَ إِلَّا عَلَى ٱللَّهِ ۖ وَأُمِرْتُ أَنْ أَكُونَ مِنَ ٱلْمُسْلِمِينَ
Transliteration fa-in tawallaytum famā sa-altukum min ajrin in ajriya illā ʿalā l-lahi wa-umir'tu an akūna mina l-mus'limīna
Yoruba Tí ẹ bá sì kọ̀yìn (sí ìrántí), èmi kò kúkú tọrọ owó-ọ̀yà kan lọ́wọ́ yín. Kò sí ẹ̀san kan fún mi (níbì kan) bí kò ṣe lọ́dọ̀ Allāhu. Wọ́n sì ti pa mí láṣẹ pé kí n̄g wà nínú àwọn mùsùlùmí.”
Verse 73
فَكَذَّبُوهُ فَنَجَّيْنَـٰهُ وَمَن مَّعَهُۥ فِى ٱلْفُلْكِ وَجَعَلْنَـٰهُمْ خَلَـٰٓئِفَ وَأَغْرَقْنَا ٱلَّذِينَ كَذَّبُوا۟ بِـَٔايَـٰتِنَا ۖ فَٱنظُرْ كَيْفَ كَانَ عَـٰقِبَةُ ٱلْمُنذَرِينَ
Transliteration fakadhabūhu fanajjaynāhu waman maʿahu fī l-ful'ki wajaʿalnāhum khalāifa wa-aghraqnā alladhīna kadhabū biāyātinā fa-unẓur kayfa kāna ʿāqibatu l-mundharīna
Yoruba Nígbà náà, wọ́n pè é ní òpùrọ́. Nítorí náà, A gbà á là, òun àti àwọn tó ń bẹ pẹ̀lú rẹ̀ nínú ọkọ̀ ojú-omi. A sì ṣe wọ́n ní àrólé (lórí ilẹ̀). A sì tẹ àwọn tó pe āyah Wa nírọ́ rì sínú agbami. Nítorí náà, wo bí ìkángun àwọn ẹni-akìlọ̀-fún ṣe rí.
Verse 74
ثُمَّ بَعَثْنَا مِنۢ بَعْدِهِۦ رُسُلًا إِلَىٰ قَوْمِهِمْ فَجَآءُوهُم بِٱلْبَيِّنَـٰتِ فَمَا كَانُوا۟ لِيُؤْمِنُوا۟ بِمَا كَذَّبُوا۟ بِهِۦ مِن قَبْلُ ۚ كَذَٰلِكَ نَطْبَعُ عَلَىٰ قُلُوبِ ٱلْمُعْتَدِينَ
Transliteration thumma baʿathnā min baʿdihi rusulan ilā qawmihim fajāūhum bil-bayināti famā kānū liyu'minū bimā kadhabū bihi min qablu kadhālika naṭbaʿu ʿalā qulūbi l-muʿ'tadīna
Yoruba Lẹ́yìn náà, A gbé àwọn Òjíṣẹ́ kan dìde sí àwọn ìjọ wọn. Wọ́n sì mú àwọn ẹ̀rí tó yanjú wá bá wọn. Àwọn náà kò kúkú gbàgbọ́ nínú ohun tí (ijọ́ Ànábì Nūh) pè nírọ́ ṣíwájú (wọn, ìyẹn ni pé, irú kan-ùn ni wọ́n).Báyẹn ni A ṣe ń fi èdídí bo ọkàn àwọn alákọyọ.
Verse 75
ثُمَّ بَعَثْنَا مِنۢ بَعْدِهِم مُّوسَىٰ وَهَـٰرُونَ إِلَىٰ فِرْعَوْنَ وَمَلَإِي۟هِۦ بِـَٔايَـٰتِنَا فَٱسْتَكْبَرُوا۟ وَكَانُوا۟ قَوْمًا مُّجْرِمِينَ
Transliteration thumma baʿathnā min baʿdihim mūsā wahārūna ilā fir'ʿawna wamala-ihi biāyātinā fa-is'takbarū wakānū qawman muj'rimīna
Yoruba Lẹ́yìn náà, lẹ́yìn wọn A fi àwọn àmì Wa rán (Ànábì) Mūsā àti Hārūn níṣẹ́ sí Fir‘aon àti àwọn ìjòyè rẹ̀. Nígbà náà, wọ́n ṣègbéraga. Wọ́n sì jẹ́ ìjọ ẹlẹ́ṣẹ̀.
Verse 76
فَلَمَّا جَآءَهُمُ ٱلْحَقُّ مِنْ عِندِنَا قَالُوٓا۟ إِنَّ هَـٰذَا لَسِحْرٌ مُّبِينٌ
Transliteration falammā jāahumu l-ḥaqu min ʿindinā qālū inna hādhā lasiḥ'run mubīnun
Yoruba Nígbà tí òdodo dé bá wọn láti ọ̀dọ̀ Wa, wọ́n wí pé: “Dájúdájú èyí ni idán pọ́nńbélé.”
Verse 77
قَالَ مُوسَىٰٓ أَتَقُولُونَ لِلْحَقِّ لَمَّا جَآءَكُمْ ۖ أَسِحْرٌ هَـٰذَا وَلَا يُفْلِحُ ٱلسَّـٰحِرُونَ
Transliteration qāla mūsā ataqūlūna lil'ḥaqqi lammā jāakum asiḥ'run hādhā walā yuf'liḥu l-sāḥirūna
Yoruba (Ànábì) Mūsā sọ pé: “Ṣé n̄ǹkan tí ẹ̀yin yóò máa wí nípa òdodo nìyẹn nígbà tí ó dé ba yín? Ṣé idán sì ni èyí! Àwọn òpìdán kò sì níí jèrè.”
Verse 78
قَالُوٓا۟ أَجِئْتَنَا لِتَلْفِتَنَا عَمَّا وَجَدْنَا عَلَيْهِ ءَابَآءَنَا وَتَكُونَ لَكُمَا ٱلْكِبْرِيَآءُ فِى ٱلْأَرْضِ وَمَا نَحْنُ لَكُمَا بِمُؤْمِنِينَ
Transliteration qālū aji'tanā litalfitanā ʿammā wajadnā ʿalayhi ābāanā watakūna lakumā l-kib'riyāu fī l-arḍi wamā naḥnu lakumā bimu'minīna
Yoruba Wọ́n wí pé: “Ṣé o wá bá wa nítorí kí o lè ṣẹ́rí wa kúrò níbi ohun tí a bá àwọn bàbá wa lórí rẹ̀ (nínú ìbọ̀rìṣà) àti nítorí kí títóbi sì lè jẹ́ tẹ̀yin méjèèjì lórí ilẹ̀? Àwa kò sì níí gba ẹ̀yin méjèèjì gbọ́.”
Verse 79
وَقَالَ فِرْعَوْنُ ٱئْتُونِى بِكُلِّ سَـٰحِرٍ عَلِيمٍ
Transliteration waqāla fir'ʿawnu i'tūnī bikulli sāḥirin ʿalīmin
Yoruba Fir‘aon wí pé: “Ẹ lọ mú gbogbo àwọn onímọ̀ nípa idán pípa wá fún mi.”
Verse 80
فَلَمَّا جَآءَ ٱلسَّحَرَةُ قَالَ لَهُم مُّوسَىٰٓ أَلْقُوا۟ مَآ أَنتُم مُّلْقُونَ
Transliteration falammā jāa l-saḥaratu qāla lahum mūsā alqū mā antum mul'qūna
Yoruba Nígbà tí àwọn òpìdán dé, (Ànábì) Mūsā sọ fún wọn pé: “Ẹ ju ohun tí ẹ fẹ́ jù sílẹ̀.”
Verse 81
فَلَمَّآ أَلْقَوْا۟ قَالَ مُوسَىٰ مَا جِئْتُم بِهِ ٱلسِّحْرُ ۖ إِنَّ ٱللَّهَ سَيُبْطِلُهُۥٓ ۖ إِنَّ ٱللَّهَ لَا يُصْلِحُ عَمَلَ ٱلْمُفْسِدِينَ
Transliteration falammā alqaw qāla mūsā mā ji'tum bihi l-siḥ'ru inna l-laha sayub'ṭiluhu inna l-laha lā yuṣ'liḥu ʿamala l-muf'sidīna
Yoruba Nígbà tí wọ́n jù ú sílẹ̀, (Ànábì) Mūsā sọ pé: “Idán ni ohun tí ẹ mú wá. Dájúdájú Allāhu sì máa bà á jẹ́. Dájúdájú Allāhu kò sì níí ṣàtúnṣe iṣẹ́ àwọn òbìlẹ̀jẹ́.
Verse 82
وَيُحِقُّ ٱللَّهُ ٱلْحَقَّ بِكَلِمَـٰتِهِۦ وَلَوْ كَرِهَ ٱلْمُجْرِمُونَ
Transliteration wayuḥiqqu l-lahu l-ḥaqa bikalimātihi walaw kariha l-muj'rimūna
Yoruba Allāhu sì máa mú òdodo ṣẹ pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ Rẹ̀, àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ìbáà kórira rẹ̀.
Verse 83
فَمَآ ءَامَنَ لِمُوسَىٰٓ إِلَّا ذُرِّيَّةٌ مِّن قَوْمِهِۦ عَلَىٰ خَوْفٍ مِّن فِرْعَوْنَ وَمَلَإِي۟هِمْ أَن يَفْتِنَهُمْ ۚ وَإِنَّ فِرْعَوْنَ لَعَالٍ فِى ٱلْأَرْضِ وَإِنَّهُۥ لَمِنَ ٱلْمُسْرِفِينَ
Transliteration famā āmana limūsā illā dhurriyyatun min qawmihi ʿalā khawfin min fir'ʿawna wamala-ihim an yaftinahum wa-inna fir'ʿawna laʿālin fī l-arḍi wa-innahu lamina l-mus'rifīna
Yoruba Nítorí náà, kò sí ẹni tó gba (Ànábì) Mūsā gbọ́ àfi àwọn àrọ́mọdọ́mọ kan nínú àwọn ènìyàn rẹ̀ pẹ̀lú ìbẹ̀rù-bojo (wọn) sí Fir‘aon àti àwọn ìjòyè wọn pé ó máa fòòró àwọn. Dájúdájú Fir‘aon kúkú ṣègbéraga lórí ilẹ̀. Àti pé, dájúdájú ó wà nínú àwọn alákọyọ.
Verse 84
وَقَالَ مُوسَىٰ يَـٰقَوْمِ إِن كُنتُمْ ءَامَنتُم بِٱللَّهِ فَعَلَيْهِ تَوَكَّلُوٓا۟ إِن كُنتُم مُّسْلِمِينَ
Transliteration waqāla mūsā yāqawmi in kuntum āmantum bil-lahi faʿalayhi tawakkalū in kuntum mus'limīna
Yoruba (Ànábì) Mūsā sọ pé: “Ẹ̀yin ènìyàn mi, tí ẹ bá jẹ́ ẹni tó gbàgbọ́ nínú Allāhu, Òun náà ni kí ẹ gbáralé tí ẹ bá jẹ́ mùsùlùmí.”
Verse 85
فَقَالُوا۟ عَلَى ٱللَّهِ تَوَكَّلْنَا رَبَّنَا لَا تَجْعَلْنَا فِتْنَةً لِّلْقَوْمِ ٱلظَّـٰلِمِينَ
Transliteration faqālū ʿalā l-lahi tawakkalnā rabbanā lā tajʿalnā fit'natan lil'qawmi l-ẓālimīna
Yoruba Nítorí náà, wọ́n sọ pé: “Allāhu la gbáralé. Olúwa wa, má ṣe wá ní àdánwòfún ìjọ alábòsí.
Verse 86
وَنَجِّنَا بِرَحْمَتِكَ مِنَ ٱلْقَوْمِ ٱلْكَـٰفِرِينَ
Transliteration wanajjinā biraḥmatika mina l-qawmi l-kāfirīna
Yoruba Kí Ó sì fi àánú Rẹ gbà wá là lọ́wọ́ ìjọ aláìgbàgbọ́.”
Verse 87
وَأَوْحَيْنَآ إِلَىٰ مُوسَىٰ وَأَخِيهِ أَن تَبَوَّءَا لِقَوْمِكُمَا بِمِصْرَ بُيُوتًا وَٱجْعَلُوا۟ بُيُوتَكُمْ قِبْلَةً وَأَقِيمُوا۟ ٱلصَّلَوٰةَ ۗ وَبَشِّرِ ٱلْمُؤْمِنِينَ
Transliteration wa-awḥaynā ilā mūsā wa-akhīhi an tabawwaā liqawmikumā bimiṣ'ra buyūtan wa-ij'ʿalū buyūtakum qib'latan wa-aqīmū l-ṣalata wabashiri l-mu'minīna
Yoruba A sì ránṣẹ́ sí (Ànábì) Mūsā àti arákùnrin rẹ̀ pé: “Kí ẹ̀yin méjèèjì mú àwọn ibùgbé fún àwọn ènìyàn yín sí ìlú Misrọ. Kí ẹ sì sọ ibùgbé yín di ibùkírun.Kí ẹ sì máa kírun. Àti pé, fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo ní ìró ìdùnnú.”
Verse 88
وَقَالَ مُوسَىٰ رَبَّنَآ إِنَّكَ ءَاتَيْتَ فِرْعَوْنَ وَمَلَأَهُۥ زِينَةً وَأَمْوَٰلًا فِى ٱلْحَيَوٰةِ ٱلدُّنْيَا رَبَّنَا لِيُضِلُّوا۟ عَن سَبِيلِكَ ۖ رَبَّنَا ٱطْمِسْ عَلَىٰٓ أَمْوَٰلِهِمْ وَٱشْدُدْ عَلَىٰ قُلُوبِهِمْ فَلَا يُؤْمِنُوا۟ حَتَّىٰ يَرَوُا۟ ٱلْعَذَابَ ٱلْأَلِيمَ
Transliteration waqāla mūsā rabbanā innaka ātayta fir'ʿawna wamala-ahu zīnatan wa-amwālan fī l-ḥayati l-dun'yā rabbanā liyuḍillū ʿan sabīlika rabbanā iṭ'mis ʿalā amwālihim wa-ush'dud ʿalā qulūbihim falā yu'minū ḥattā yarawū l-ʿadhāba l-alīma
Yoruba (Ànábì) Mūsā sọ pé: “Olúwa wa, dájúdájú Ìwọ l’O fún Fir‘aon àti àwọn ìjòyè rẹ̀ ní ọ̀ṣọ́ àti dúkìá nínú ìṣẹ̀mí ayé. Olúwa wa, (O fún wọn) torí kí wọ́n lè ṣẹ́rí àwọn ènìyàn kúrò lójú ọ̀nà (ẹ̀sìn) Rẹ.Olúwa wa, pa dúkìá wọn rẹ́, kí O sì mú ọkàn wọn le, kí wọ́n má gbàgbọ́ mọ́ títí wọn fi máa rí ìyà ẹlẹ́ta-eléro.”
Verse 89
قَالَ قَدْ أُجِيبَت دَّعْوَتُكُمَا فَٱسْتَقِيمَا وَلَا تَتَّبِعَآنِّ سَبِيلَ ٱلَّذِينَ لَا يَعْلَمُونَ
Transliteration qāla qad ujībat daʿwatukumā fa-is'taqīmā walā tattabiʿānni sabīla alladhīna lā yaʿlamūna
Yoruba (Allāhu) sọ pé: “Dájúdájú Mo ti gba àdúà ẹ̀yin méjèèjì. Nítorí náà, kí ẹ̀yin méjèèjì dúró ṣinṣin. Ẹ má ṣe tẹ̀lé ojú ọ̀nà àwọn tí kò nímọ̀.”
Verse 90
۞ وَجَـٰوَزْنَا بِبَنِىٓ إِسْرَٰٓءِيلَ ٱلْبَحْرَ فَأَتْبَعَهُمْ فِرْعَوْنُ وَجُنُودُهُۥ بَغْيًا وَعَدْوًا ۖ حَتَّىٰٓ إِذَآ أَدْرَكَهُ ٱلْغَرَقُ قَالَ ءَامَنتُ أَنَّهُۥ لَآ إِلَـٰهَ إِلَّا ٱلَّذِىٓ ءَامَنَتْ بِهِۦ بَنُوٓا۟ إِسْرَٰٓءِيلَ وَأَنَا۠ مِنَ ٱلْمُسْلِمِينَ
Transliteration wajāwaznā bibanī is'rāīla l-baḥra fa-atbaʿahum fir'ʿawnu wajunūduhu baghyan waʿadwan ḥattā idhā adrakahu l-gharaqu qāla āmantu annahu lā ilāha illā alladhī āmanat bihi banū is'rāīla wa-anā mina l-mus'limīna
Yoruba A mú àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl la agbami òkun já. Fir‘aon àti àwọn ọmọ ogun rẹ̀ sì gbá tọ̀ wọ́n lẹ́yìn, ní ti ìlara àti ìtayọ ẹnu-ààlà, títí ìtẹ̀rì sínú agbami òkun fi bá a. Ó sì wí pé: “Mo gbàgbọ́ pé dájúdájú kò sí ọlọ́hun kan tí a gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo àyàfi Ẹni tí àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl gbàgbọ́. Mo sì wà nínú àwọn mùsùlùmí.”1
Verse 91
ءَآلْـَٔـٰنَ وَقَدْ عَصَيْتَ قَبْلُ وَكُنتَ مِنَ ٱلْمُفْسِدِينَ
Transliteration āl'āna waqad ʿaṣayta qablu wakunta mina l-muf'sidīna
Yoruba Ṣé nísinsìn yìí, tí ìwọ ti yapa ṣíwájú, tí o sì wà nínú àwọn òbìlẹ̀jẹ́?
Verse 92
فَٱلْيَوْمَ نُنَجِّيكَ بِبَدَنِكَ لِتَكُونَ لِمَنْ خَلْفَكَ ءَايَةً ۚ وَإِنَّ كَثِيرًا مِّنَ ٱلنَّاسِ عَنْ ءَايَـٰتِنَا لَغَـٰفِلُونَ
Transliteration fal-yawma nunajjīka bibadanika litakūna liman khalfaka āyatan wa-inna kathīran mina l-nāsi ʿan āyātinā laghāfilūna
Yoruba Nítorí náà, ní òní ni A óò gbé òkú rẹ jáde sí orí ilẹ̀ téńté nítorí kí o lè jẹ́ àmì (fèyíkọ́gbọ́n) fún àwọn tó ń bọ̀ lẹ́yìn rẹ. Dájúdájú ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ nínú àwọn ènìyàn mà ni afọ́nú-fọ́ra nípa àwọn āyah Wa.
Verse 93
وَلَقَدْ بَوَّأْنَا بَنِىٓ إِسْرَٰٓءِيلَ مُبَوَّأَ صِدْقٍ وَرَزَقْنَـٰهُم مِّنَ ٱلطَّيِّبَـٰتِ فَمَا ٱخْتَلَفُوا۟ حَتَّىٰ جَآءَهُمُ ٱلْعِلْمُ ۚ إِنَّ رَبَّكَ يَقْضِى بَيْنَهُمْ يَوْمَ ٱلْقِيَـٰمَةِ فِيمَا كَانُوا۟ فِيهِ يَخْتَلِفُونَ
Transliteration walaqad bawwanā banī is'rāīla mubawwa-a ṣid'qin warazaqnāhum mina l-ṭayibāti famā ikh'talafū ḥattā jāahumu l-ʿil'mu inna rabbaka yaqḍī baynahum yawma l-qiyāmati fīmā kānū fīhi yakhtalifūna
Yoruba A kúkú ṣe ibùgbé fún àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl ní ibùgbé dáadáa. A sì pèsè fún wọn nínú àwọn n̄ǹkan dáadáa. Nígbà náà, wọn kò yapa-ẹnu (lórí ’Islām) títí ìmọ̀ fi dé bá wọn.Dájúdájú Olúwa rẹ yóò ṣèdájọ́ láààrin wọn ní Ọjọ́ Àjíǹde nípa ohun tí wọ́n ń yapa-ẹnu lórí rẹ̀.
Verse 94
فَإِن كُنتَ فِى شَكٍّ مِّمَّآ أَنزَلْنَآ إِلَيْكَ فَسْـَٔلِ ٱلَّذِينَ يَقْرَءُونَ ٱلْكِتَـٰبَ مِن قَبْلِكَ ۚ لَقَدْ جَآءَكَ ٱلْحَقُّ مِن رَّبِّكَ فَلَا تَكُونَنَّ مِنَ ٱلْمُمْتَرِينَ
Transliteration fa-in kunta fī shakkin mimmā anzalnā ilayka fasali alladhīna yaqraūna l-kitāba min qablika laqad jāaka l-ḥaqu min rabbika falā takūnanna mina l-mum'tarīna
Yoruba Tí o bá wà nínú iyèméjì nípa n̄ǹkan tí A sọ̀kalẹ̀ fún ọ (pé orúkọ rẹ àti àsọtẹ́lẹ̀ nípa rẹ wà nínú at-Taorāt àti al-’Injīl), bi àwọn tó ń ka Tírà ṣíwájú rẹ léèrè wò.Dájúdájú òdodo ti dé bá ọ láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ. Nítorí náà, o ò gbọdọ̀ wà lára àwọn oníyèméjì.
Verse 95
وَلَا تَكُونَنَّ مِنَ ٱلَّذِينَ كَذَّبُوا۟ بِـَٔايَـٰتِ ٱللَّهِ فَتَكُونَ مِنَ ٱلْخَـٰسِرِينَ
Transliteration walā takūnanna mina alladhīna kadhabū biāyāti l-lahi fatakūna mina l-khāsirīna
Yoruba O ò gbọdọ̀ wà lára àwọn tó pe àwọn āyah Allāhu nírọ́, nítorí kí o má baà wà lára àwọn ẹni òfò.
Verse 96
إِنَّ ٱلَّذِينَ حَقَّتْ عَلَيْهِمْ كَلِمَتُ رَبِّكَ لَا يُؤْمِنُونَ
Transliteration inna alladhīna ḥaqqat ʿalayhim kalimatu rabbika lā yu'minūna
Yoruba Dájúdájú àwọn tí ọ̀rọ̀ Olúwa rẹ ti kò lé lórí, wọn kò níí gbàgbọ́,
Verse 97
وَلَوْ جَآءَتْهُمْ كُلُّ ءَايَةٍ حَتَّىٰ يَرَوُا۟ ٱلْعَذَابَ ٱلْأَلِيمَ
Transliteration walaw jāathum kullu āyatin ḥattā yarawū l-ʿadhāba l-alīma
Yoruba gbogbo āyah ìbáà dé bá wọn, títí wọ́n máa fi rí ìyà ẹlẹ́ta-eléro.1
Verse 98
فَلَوْلَا كَانَتْ قَرْيَةٌ ءَامَنَتْ فَنَفَعَهَآ إِيمَـٰنُهَآ إِلَّا قَوْمَ يُونُسَ لَمَّآ ءَامَنُوا۟ كَشَفْنَا عَنْهُمْ عَذَابَ ٱلْخِزْىِ فِى ٱلْحَيَوٰةِ ٱلدُّنْيَا وَمَتَّعْنَـٰهُمْ إِلَىٰ حِينٍ
Transliteration falawlā kānat qaryatun āmanat fanafaʿahā īmānuhā illā qawma yūnusa lammā āmanū kashafnā ʿanhum ʿadhāba l-khiz'yi fī l-ḥayati l-dun'yā wamattaʿnāhum ilā ḥīnin
Yoruba Kí ó sì jẹ́ pé ìlú kàn gbàgbọ́ (lásìkò ìsọ̀kalẹ̀ ìyà), kí ìgbàgbọ́ rẹ̀ sì ṣe é ní àǹfààní (kò kúkú sí) àfi ìjọ (Ànábì) Yūnus (nítorí pé), nígbà tí wọ́n gbàgbọ́, A mú àbùkù ìyà kúrò fún wọn nínú ìṣẹ̀mí ayé. A sì jẹ́ kí wọ́n jẹ ìgbádùn ayé fún ìgbà díẹ̀.
Verse 99
وَلَوْ شَآءَ رَبُّكَ لَـَٔامَنَ مَن فِى ٱلْأَرْضِ كُلُّهُمْ جَمِيعًا ۚ أَفَأَنتَ تُكْرِهُ ٱلنَّاسَ حَتَّىٰ يَكُونُوا۟ مُؤْمِنِينَ
Transliteration walaw shāa rabbuka laāmana man fī l-arḍi kulluhum jamīʿan afa-anta tuk'rihu l-nāsa ḥattā yakūnū mu'minīna
Yoruba Tí ó bá jẹ́ pé Olúwa rẹ bá fẹ́, gbogbo àwọn tí ń bẹ lórí ilẹ̀ pátápátá ìbá gbàgbọ́. Nítorí náà, ṣé ìwọ lo máa jẹ àwọn ènìyàn nípá títí wọn yóò fi di onígbàgbọ́ òdodo ni?
Verse 100
وَمَا كَانَ لِنَفْسٍ أَن تُؤْمِنَ إِلَّا بِإِذْنِ ٱللَّهِ ۚ وَيَجْعَلُ ٱلرِّجْسَ عَلَى ٱلَّذِينَ لَا يَعْقِلُونَ
Transliteration wamā kāna linafsin an tu'mina illā bi-idh'ni l-lahi wayajʿalu l-rij'sa ʿalā alladhīna lā yaʿqilūna
Yoruba Ẹ̀mí kan kò lè gbàgbọ́ àfi pẹ̀lú ìyọ̀ǹda Allāhu. Ó sì máa fi ìyà jẹ àwọn tí kò ṣe làákàyè.1
Verse 101
قُلِ ٱنظُرُوا۟ مَاذَا فِى ٱلسَّمَـٰوَٰتِ وَٱلْأَرْضِ ۚ وَمَا تُغْنِى ٱلْـَٔايَـٰتُ وَٱلنُّذُرُ عَن قَوْمٍ لَّا يُؤْمِنُونَ
Transliteration quli unẓurū mādhā fī l-samāwāti wal-arḍi wamā tugh'nī l-āyātu wal-nudhuru ʿan qawmin lā yu'minūna
Yoruba Sọ pé: “Ẹ wòye sí n̄ǹkan tí ń bẹ nínú àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Àwọn āyah àti ìkìlọ̀ kò sì níí rọ ìjọ aláìgbàgbọ́ lọ́rọ̀.”
Verse 102
فَهَلْ يَنتَظِرُونَ إِلَّا مِثْلَ أَيَّامِ ٱلَّذِينَ خَلَوْا۟ مِن قَبْلِهِمْ ۚ قُلْ فَٱنتَظِرُوٓا۟ إِنِّى مَعَكُم مِّنَ ٱلْمُنتَظِرِينَ
Transliteration fahal yantaẓirūna illā mith'la ayyāmi alladhīna khalaw min qablihim qul fa-intaẓirū innī maʿakum mina l-muntaẓirīna
Yoruba Nítorí náà, ṣé wọ́n tún ń retí (n̄ǹkan mìíràn) ni bí kò ṣe (ìparun) irú ti ọjọ́ àwọn tó ré kọjá lọ ṣíwájú wọn. Sọ pé: “Ẹ máa retí nígbà náà. Dájúdájú èmi náà wà pẹ̀lú yín nínú àwọn olùretí.”
Verse 103
ثُمَّ نُنَجِّى رُسُلَنَا وَٱلَّذِينَ ءَامَنُوا۟ ۚ كَذَٰلِكَ حَقًّا عَلَيْنَا نُنجِ ٱلْمُؤْمِنِينَ
Transliteration thumma nunajjī rusulanā wa-alladhīna āmanū kadhālika ḥaqqan ʿalaynā nunji l-mu'minīna
Yoruba Lẹ́yìn náà, A óò gba àwọn Òjíṣẹ́ Wa àti àwọn tó gbàgbọ́ lódodo là. Báyẹn ní ó ṣe jẹ́ ojúṣe Wa láti gba àwọn onígbàgbọ́ òdodo là.
Verse 104
قُلْ يَـٰٓأَيُّهَا ٱلنَّاسُ إِن كُنتُمْ فِى شَكٍّ مِّن دِينِى فَلَآ أَعْبُدُ ٱلَّذِينَ تَعْبُدُونَ مِن دُونِ ٱللَّهِ وَلَـٰكِنْ أَعْبُدُ ٱللَّهَ ٱلَّذِى يَتَوَفَّىٰكُمْ ۖ وَأُمِرْتُ أَنْ أَكُونَ مِنَ ٱلْمُؤْمِنِينَ
Transliteration qul yāayyuhā l-nāsu in kuntum fī shakkin min dīnī falā aʿbudu alladhīna taʿbudūna min dūni l-lahi walākin aʿbudu l-laha alladhī yatawaffākum wa-umir'tu an akūna mina l-mu'minīna
Yoruba Sọ pé: “Ẹ̀yin ènìyàn, tí ẹ bá wà nínú iyèméjì nípa ẹ̀sìn mi. Nígbà náà, èmi kò níí jọ́sìn fún àwọn tí ẹ̀ ń jọ́sìn fún lẹ́yìn Allāhu. Ṣùgbọ́n èmi yóò máa jọ́sìn fún Allāhu, Ẹni tí Ó máa gba ẹ̀mí yín. Wọ́n sì pa mí ní àṣẹ pé kí n̄g wà nínú àwọn onígbàgbọ́ òdodo.
Verse 105
وَأَنْ أَقِمْ وَجْهَكَ لِلدِّينِ حَنِيفًا وَلَا تَكُونَنَّ مِنَ ٱلْمُشْرِكِينَ
Transliteration wa-an aqim wajhaka lilddīni ḥanīfan walā takūnanna mina l-mush'rikīna
Yoruba (Wọ́n tún pa mí láṣẹ pé): “Dojú rẹ kọ ẹ̀sìn náà, (kí o jẹ́) olùdúró-déédé-nínú-ẹ̀sìn.Ìwọ kò sì gbọdọ̀ wà nínú àwọn ọ̀ṣẹbọ.
Verse 106
وَلَا تَدْعُ مِن دُونِ ٱللَّهِ مَا لَا يَنفَعُكَ وَلَا يَضُرُّكَ ۖ فَإِن فَعَلْتَ فَإِنَّكَ إِذًا مِّنَ ٱلظَّـٰلِمِينَ
Transliteration walā tadʿu min dūni l-lahi mā lā yanfaʿuka walā yaḍurruka fa-in faʿalta fa-innaka idhan mina l-ẓālimīna
Yoruba Àti pé má ṣe pè lẹ́yìn Allāhu n̄ǹkan tí kò lè ṣe ọ́ ní àǹfààní, tí kò sì lè kó ìnira bá ọ. Tí o bá ṣe bẹ́ẹ̀ nígbà náà, dájúdájú ìwọ ti wà nínú àwọn alábòsí.”
Verse 107
وَإِن يَمْسَسْكَ ٱللَّهُ بِضُرٍّ فَلَا كَاشِفَ لَهُۥٓ إِلَّا هُوَ ۖ وَإِن يُرِدْكَ بِخَيْرٍ فَلَا رَآدَّ لِفَضْلِهِۦ ۚ يُصِيبُ بِهِۦ مَن يَشَآءُ مِنْ عِبَادِهِۦ ۚ وَهُوَ ٱلْغَفُورُ ٱلرَّحِيمُ
Transliteration wa-in yamsaska l-lahu biḍurrin falā kāshifa lahu illā huwa wa-in yurid'ka bikhayrin falā rādda lifaḍlihi yuṣību bihi man yashāu min ʿibādihi wahuwa l-ghafūru l-raḥīmu
Yoruba Tí Allāhu bá mú ìnira bá ọ, kò sí ẹni tí ó lè mú un kúrò àfi Òun. Tí Ó bá sì gbèrò oore kan pẹ̀lú rẹ, kò sí ẹni tí ó lè dá oore Rẹ̀ padà. Ó ń ṣoore fún ẹni tí Ó bá fẹ́ nínú àwọn ẹrúsìn Rẹ̀. Òun ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.
Verse 108
قُلْ يَـٰٓأَيُّهَا ٱلنَّاسُ قَدْ جَآءَكُمُ ٱلْحَقُّ مِن رَّبِّكُمْ ۖ فَمَنِ ٱهْتَدَىٰ فَإِنَّمَا يَهْتَدِى لِنَفْسِهِۦ ۖ وَمَن ضَلَّ فَإِنَّمَا يَضِلُّ عَلَيْهَا ۖ وَمَآ أَنَا۠ عَلَيْكُم بِوَكِيلٍ
Transliteration qul yāayyuhā l-nāsu qad jāakumu l-ḥaqu min rabbikum famani ih'tadā fa-innamā yahtadī linafsihi waman ḍalla fa-innamā yaḍillu ʿalayhā wamā anā ʿalaykum biwakīlin
Yoruba Sọ pé: “Ẹ̀yin ènìyàn, dájúdájú òdodo ti dé ba yín láti ọ̀dọ̀ Olúwa yín. Nítorí náà, ẹnikẹ́ni tí ó bá mọ̀nà, ó mọ̀nà fún ẹ̀mí ara rẹ̀. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì ṣìnà, ó ṣìnà fún ẹ̀mí ara rẹ̀. Èmi sì kọ́ ni olùṣọ́ fún yín.”
Verse 109
وَٱتَّبِعْ مَا يُوحَىٰٓ إِلَيْكَ وَٱصْبِرْ حَتَّىٰ يَحْكُمَ ٱللَّهُ ۚ وَهُوَ خَيْرُ ٱلْحَـٰكِمِينَ
Transliteration wa-ittabiʿ mā yūḥā ilayka wa-iṣ'bir ḥattā yaḥkuma l-lahu wahuwa khayru l-ḥākimīna
Yoruba Tẹ̀lé ohun tí A fi ránṣẹ́ sí ọ nínú ìmísí. Kí o sì ṣe sùúrù títí Allāhu yóò fi ṣèdájọ́. Òun sì lóore julọ nínú àwọn olùdájọ́.
Read Surah Yunus in another language
- English (word by word)
- Albanian
- Amazigh
- Amharic
- Assamese
- Azerbaijani
- Bambara
- Bangla
- Bosnian
- Bulgarian
- Chechen
- Chinese
- Czech
- Dari
- Dhivehi
- Dutch
- Finnish
- French
- German
- Gujarati
- Hausa
- Hebrew
- Hindi
- Indonesian
- Italian
- Japanese
- Kannada
- Kazakh
- Khmer
- Kinyarwanda
- Korean
- Kurdish
- Luganda
- Malay
- Malayalam
- Maranao
- Marathi
- Nepali
- Norwegian
- Oromo
- Pashto
- Persian
- Polish
- Portuguese
- Romanian
- Russian
- Sindhi
- Sinhala
- Somali
- Spanish
- Swahili
- Swedish
- Tagalog
- Tajik
- Tamil
- Tatar
- Telugu
- Thai
- Turkish
- Ukrainian
- Urdu
- Uyghur
- Uzbek
- Vietnamese
- Yao
All 114 surahs in Yoruba: the Qur’an in Yoruba.
Yoruba translation: Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni, from Quran.com. Transliteration: Quran.com. Recitation: Mishary Alafasy, from EveryAyah.com. MyDugsi is a learning aid, not a replacement for a qualified teacher.