MyDugsiStart learning

Surah Taha in Yoruba: translation and audio

Surah 20 · طه · Ta-Ha · 135 verses

Surah Taha verse by verse: the Arabic with a recitation you can repeat, the transliteration, and the Yoruba translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni. For the meaning of every word, see Surah Taha word by word in English.

Verse 1

طه

Transliteration tta-ha

Yoruba Tọ̄ hā. (Allāhu ló mọ ohun tí Ó gbàlérò pẹ̀lú àwọn háràfí náà.)1

Verse 2

مَآ أَنزَلْنَا عَلَيْكَ ٱلْقُرْءَانَ لِتَشْقَىٰٓ

Transliteration mā anzalnā ʿalayka l-qur'āna litashqā

Yoruba A kò sọ al-Ƙur’ān kalẹ̀ fún ọ láti kó wàhálà bá ọ.

Verse 3

إِلَّا تَذْكِرَةً لِّمَن يَخْشَىٰ

Transliteration illā tadhkiratan liman yakhshā

Yoruba Bí kò ṣe pé ó jẹ́ ìrántí fún ẹni tó ń páyà (Allāhu).

Verse 4

تَنزِيلًا مِّمَّنْ خَلَقَ ٱلْأَرْضَ وَٱلسَّمَـٰوَٰتِ ٱلْعُلَى

Transliteration tanzīlan mimman khalaqa l-arḍa wal-samāwāti l-ʿulā

Yoruba (Ó jẹ́) ìmísí tó sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Ẹni tí Ó dá ilẹ̀ àti àwọn sánmọ̀ gíga.

Verse 5

ٱلرَّحْمَـٰنُ عَلَى ٱلْعَرْشِ ٱسْتَوَىٰ

Transliteration al-raḥmānu ʿalā l-ʿarshi is'tawā

Yoruba Àjọkẹ́-ayé gúnwà sórí Ìtẹ́-ọlá.

Verse 6

لَهُۥ مَا فِى ٱلسَّمَـٰوَٰتِ وَمَا فِى ٱلْأَرْضِ وَمَا بَيْنَهُمَا وَمَا تَحْتَ ٱلثَّرَىٰ

Transliteration lahu mā fī l-samāwāti wamā fī l-arḍi wamā baynahumā wamā taḥta l-tharā

Yoruba TiRẹ̀ ni ohunkóhun tó wà nínú àwọn sánmọ̀, ohunkóhun tó wà nínú ilẹ̀ àti ohunkóhun tó wà láààrin méjèèjì àti ohunkóhun tó wà lábẹ́ ilẹ̀.

Verse 7

وَإِن تَجْهَرْ بِٱلْقَوْلِ فَإِنَّهُۥ يَعْلَمُ ٱلسِّرَّ وَأَخْفَى

Transliteration wa-in tajhar bil-qawli fa-innahu yaʿlamu l-sira wa-akhfā

Yoruba Tí o bá sọ ọ̀rọ̀ jáde, dájúdájú (Allāhu) mọ ìkọ̀kọ̀ àti ohun tí ó (tún) pamọ́ jùlọ.

Verse 8

ٱللَّهُ لَآ إِلَـٰهَ إِلَّا هُوَ ۖ لَهُ ٱلْأَسْمَآءُ ٱلْحُسْنَىٰ

Transliteration al-lahu lā ilāha illā huwa lahu l-asmāu l-ḥus'nā

Yoruba Allāhu, kò sí ọlọ́hun kan tí a gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo àyàfi Òun. TiRẹ̀ ni àwọn orúkọ tó dára jùlọ.

Verse 9

وَهَلْ أَتَىٰكَ حَدِيثُ مُوسَىٰٓ

Transliteration wahal atāka ḥadīthu mūsā

Yoruba Ǹjẹ́ ọ̀rọ̀ (Ànábì) Mūsā dé ọ̀dọ̀ rẹ?

Verse 10

إِذْ رَءَا نَارًا فَقَالَ لِأَهْلِهِ ٱمْكُثُوٓا۟ إِنِّىٓ ءَانَسْتُ نَارًا لَّعَلِّىٓ ءَاتِيكُم مِّنْهَا بِقَبَسٍ أَوْ أَجِدُ عَلَى ٱلنَّارِ هُدًى

Transliteration idh raā nāran faqāla li-ahlihi um'kuthū innī ānastu nāran laʿallī ātīkum min'hā biqabasin aw ajidu ʿalā l-nāri hudan

Yoruba (Rántí) nígbà tí ó rí iná kan, ó sọ fún àwọn ará ilé rẹ̀ pé: “Ẹ dúró síbí. Dájúdájú èmi rí iná kan. Ó ṣeé ṣe kí n̄g rí ògúnná mú wá fún yín nínú rẹ̀ tàbí kí n̄g rí ojú ọ̀nà kan nítòsí iná náà.”

Verse 11

فَلَمَّآ أَتَىٰهَا نُودِىَ يَـٰمُوسَىٰٓ

Transliteration falammā atāhā nūdiya yāmūsā

Yoruba Nígbà tí ó dé ibẹ̀, A pè é “Mūsā,

Verse 12

إِنِّىٓ أَنَا۠ رَبُّكَ فَٱخْلَعْ نَعْلَيْكَ ۖ إِنَّكَ بِٱلْوَادِ ٱلْمُقَدَّسِ طُوًى

Transliteration innī anā rabbuka fa-ikh'laʿ naʿlayka innaka bil-wādi l-muqadasi ṭuwan

Yoruba Dájúdájú Èmi ni Olúwa rẹ. Nítorí náà, bọ́ bàtà rẹ méjèèjì sílẹ̀.Dájúdájú ìwọ wà ní àfonífojì mímọ́, Tuwā.

Verse 13

وَأَنَا ٱخْتَرْتُكَ فَٱسْتَمِعْ لِمَا يُوحَىٰٓ

Transliteration wa-anā ikh'tartuka fa-is'tamiʿ limā yūḥā

Yoruba Àti pé Èmi ṣà ọ́ lẹ́ṣà. Nítorí náà, fi etí sí ohun tí A máa fi ránṣẹ́ sí ọ nínú ìmísí.

Verse 14

إِنَّنِىٓ أَنَا ٱللَّهُ لَآ إِلَـٰهَ إِلَّآ أَنَا۠ فَٱعْبُدْنِى وَأَقِمِ ٱلصَّلَوٰةَ لِذِكْرِىٓ

Transliteration innanī anā l-lahu lā ilāha illā anā fa-uʿ'bud'nī wa-aqimi l-ṣalata lidhik'rī

Yoruba Dájúdájú Èmi ni Allāhu. Kò sí ọlọ́hun kan tí ẹ gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo àyàfi Èmi. Nítorí náà, jọ́sìn fún Mi. Kí o sì kírun fún ìrántí Mi.1

Verse 15

إِنَّ ٱلسَّاعَةَ ءَاتِيَةٌ أَكَادُ أُخْفِيهَا لِتُجْزَىٰ كُلُّ نَفْسٍۭ بِمَا تَسْعَىٰ

Transliteration inna l-sāʿata ātiyatun akādu ukh'fīhā lituj'zā kullu nafsin bimā tasʿā

Yoruba Dájúdájú Àkókò náà ń bọ̀. Ó súnmọ́ kí N̄g ṣàfi hànrẹ̀ (pẹ̀lú àwọn àmì kan. Àkókò náà wà fún) kí Á lè san ẹ̀mí kọ̀ọ̀kan ní ẹ̀san n̄ǹkan tí ó ṣe níṣẹ́.

Verse 16

فَلَا يَصُدَّنَّكَ عَنْهَا مَن لَّا يُؤْمِنُ بِهَا وَٱتَّبَعَ هَوَىٰهُ فَتَرْدَىٰ

Transliteration falā yaṣuddannaka ʿanhā man lā yu'minu bihā wa-ittabaʿa hawāhu fatardā

Yoruba Nítorí náà, ẹni tí kò gbàgbọ́ nínú rẹ̀, tí ó sì tẹ̀lé ìfẹ́-inú rẹ̀, má ṣe jẹ́ kí ó ṣẹ́rí rẹ kúrò níbẹ̀, kí o má baà parun.

Verse 17

وَمَا تِلْكَ بِيَمِينِكَ يَـٰمُوسَىٰ

Transliteration wamā til'ka biyamīnika yāmūsā

Yoruba Kí ni ìyẹn lọ́wọ́ ọ̀tún rẹ, Mūsā?”

Verse 18

قَالَ هِىَ عَصَاىَ أَتَوَكَّؤُا۟ عَلَيْهَا وَأَهُشُّ بِهَا عَلَىٰ غَنَمِى وَلِىَ فِيهَا مَـَٔارِبُ أُخْرَىٰ

Transliteration qāla hiya ʿaṣāya atawakka-u ʿalayhā wa-ahushu bihā ʿalā ghanamī waliya fīhā maāribu ukh'rā

Yoruba Ó sọ pé: “Ọ̀pá mi ni. Mò ń fi rọ̀gbọ̀kú. Mo tún ń fi já ewé fún àwọn àgùtàn mi. Mo sì tún ń lò ó fún àwọn bùkátà mìíràn.”

Verse 19

قَالَ أَلْقِهَا يَـٰمُوسَىٰ

Transliteration qāla alqihā yāmūsā

Yoruba (Allāhu) sọ pé: “Jù ú sílẹ̀, Mūsā.”

Verse 20

فَأَلْقَىٰهَا فَإِذَا هِىَ حَيَّةٌ تَسْعَىٰ

Transliteration fa-alqāhā fa-idhā hiya ḥayyatun tasʿā

Yoruba Nígbà náà, ó jù ú sílẹ̀. Ó sì di ejò tó ń sáré.

Verse 21

قَالَ خُذْهَا وَلَا تَخَفْ ۖ سَنُعِيدُهَا سِيرَتَهَا ٱلْأُولَىٰ

Transliteration qāla khudh'hā walā takhaf sanuʿīduhā sīratahā l-ūlā

Yoruba (Allāhu) sọ pé: “Mú un dání, má sì ṣe bẹ̀rù. A máa dá a padà sí ìrísí rẹ̀ àkọ́kọ́.

Verse 22

وَٱضْمُمْ يَدَكَ إِلَىٰ جَنَاحِكَ تَخْرُجْ بَيْضَآءَ مِنْ غَيْرِ سُوٓءٍ ءَايَةً أُخْرَىٰ

Transliteration wa-uḍ'mum yadaka ilā janāḥika takhruj bayḍāa min ghayri sūin āyatan ukh'rā

Yoruba Fi ọwọ́ rẹ mọ́ (abẹ́) apá rẹ, ó máa jáde ní funfun, tí kì í ṣe taburú. (Ó tún jẹ́) àmì mìíràn.

Verse 23

لِنُرِيَكَ مِنْ ءَايَـٰتِنَا ٱلْكُبْرَى

Transliteration linuriyaka min āyātinā l-kub'rā

Yoruba Kí Á lè fi èyí tó tóbi nínú àwọn àmì Wa hàn ọ́.

Verse 24

ٱذْهَبْ إِلَىٰ فِرْعَوْنَ إِنَّهُۥ طَغَىٰ

Transliteration idh'hab ilā fir'ʿawna innahu ṭaghā

Yoruba Lọ sí ọ̀dọ̀ Fir‘aon. Dájúdájú ó ti tayọ ẹnu-ààlà.”

Verse 25

قَالَ رَبِّ ٱشْرَحْ لِى صَدْرِى

Transliteration qāla rabbi ish'raḥ lī ṣadrī

Yoruba (Ànábì Mūsā) sọ pé: “Olúwa mi, ṣí ọkàn mi payá fún mi.

Verse 26

وَيَسِّرْ لِىٓ أَمْرِى

Transliteration wayassir lī amrī

Yoruba Ṣọ̀rọ̀ mi dìrọ̀rùn fún mi.

Verse 27

وَٱحْلُلْ عُقْدَةً مِّن لِّسَانِى

Transliteration wa-uḥ'lul ʿuq'datan min lisānī

Yoruba Tú kókó orí ahọ́n mi

Verse 28

يَفْقَهُوا۟ قَوْلِى

Transliteration yafqahū qawlī

Yoruba kí wọ́n máa gbọ́ ọ̀rọ̀ mi yé.

Verse 29

وَٱجْعَل لِّى وَزِيرًا مِّنْ أَهْلِى

Transliteration wa-ij'ʿal lī wazīran min ahlī

Yoruba Àti pé fún mi ní amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ kan nínú àwọn ará ilé mi,

Verse 30

هَـٰرُونَ أَخِى

Transliteration hārūna akhī

Yoruba Hārūn, arákùnrin mi ni.

Verse 31

ٱشْدُدْ بِهِۦٓ أَزْرِى

Transliteration ush'dud bihi azrī

Yoruba Fi kún mi lọ́wọ́.

Verse 32

وَأَشْرِكْهُ فِىٓ أَمْرِى

Transliteration wa-ashrik'hu fī amrī

Yoruba Fi ṣakẹgbẹ́ mi nínú iṣẹ́ mi

Verse 33

كَىْ نُسَبِّحَكَ كَثِيرًا

Transliteration kay nusabbiḥaka kathīran

Yoruba torí kí á lè ṣàfọ̀mọ́ (orúkọ) Rẹ ní ọ̀pọ̀lọ́pọ̀,

Verse 34

وَنَذْكُرَكَ كَثِيرًا

Transliteration wanadhkuraka kathīran

Yoruba kí á tún lè ṣèrántí Rẹ ní ọ̀pọ̀lọ́pọ̀.

Verse 35

إِنَّكَ كُنتَ بِنَا بَصِيرًا

Transliteration innaka kunta binā baṣīran

Yoruba Dájúdájú Ìwọ ń rí wa.”

Verse 36

قَالَ قَدْ أُوتِيتَ سُؤْلَكَ يَـٰمُوسَىٰ

Transliteration qāla qad ūtīta su'laka yāmūsā

Yoruba (Allāhu) sọ pé: “Dájúdájú A ti fún ọ ní ìbéèrè rẹ, Mūsā.

Verse 37

وَلَقَدْ مَنَنَّا عَلَيْكَ مَرَّةً أُخْرَىٰٓ

Transliteration walaqad manannā ʿalayka marratan ukh'rā

Yoruba Àti pé dájúdájú A ti ṣe oore fún ọ nígbà kan rí.

Verse 38

إِذْ أَوْحَيْنَآ إِلَىٰٓ أُمِّكَ مَا يُوحَىٰٓ

Transliteration idh awḥaynā ilā ummika mā yūḥā

Yoruba (Rántí) nígbà tí A ṣípayá ohun tí A ṣípayá fún ìyá rẹ

Verse 39

أَنِ ٱقْذِفِيهِ فِى ٱلتَّابُوتِ فَٱقْذِفِيهِ فِى ٱلْيَمِّ فَلْيُلْقِهِ ٱلْيَمُّ بِٱلسَّاحِلِ يَأْخُذْهُ عَدُوٌّ لِّى وَعَدُوٌّ لَّهُۥ ۚ وَأَلْقَيْتُ عَلَيْكَ مَحَبَّةً مِّنِّى وَلِتُصْنَعَ عَلَىٰ عَيْنِىٓ

Transliteration ani iq'dhifīhi fī l-tābūti fa-iq'dhifīhi fī l-yami falyul'qihi l-yamu bil-sāḥili yakhudh'hu ʿaduwwun lī waʿaduwwun lahu wa-alqaytu ʿalayka maḥabbatan minnī walituṣ'naʿa ʿalā ʿaynī

Yoruba pé: “Ju Mūsā sínú àpótí. Kí o sì gbé e jù sínú odò. Odò yó sì gbé e jù sí etí odò. Ọ̀tá Mi àti ọ̀tá rẹ̀ sì máa gbé e.” Mo sì da ìfẹ́ láti ọ̀dọ̀ Mi bò ọ́ nítorí kí wọ́n lè tọ́jú rẹ lójú Mi.”

Verse 40

إِذْ تَمْشِىٓ أُخْتُكَ فَتَقُولُ هَلْ أَدُلُّكُمْ عَلَىٰ مَن يَكْفُلُهُۥ ۖ فَرَجَعْنَـٰكَ إِلَىٰٓ أُمِّكَ كَىْ تَقَرَّ عَيْنُهَا وَلَا تَحْزَنَ ۚ وَقَتَلْتَ نَفْسًا فَنَجَّيْنَـٰكَ مِنَ ٱلْغَمِّ وَفَتَنَّـٰكَ فُتُونًا ۚ فَلَبِثْتَ سِنِينَ فِىٓ أَهْلِ مَدْيَنَ ثُمَّ جِئْتَ عَلَىٰ قَدَرٍ يَـٰمُوسَىٰ

Transliteration idh tamshī ukh'tuka fataqūlu hal adullukum ʿalā man yakfuluhu farajaʿnāka ilā ummika kay taqarra ʿaynuhā walā taḥzana waqatalta nafsan fanajjaynāka mina l-ghami wafatannāka futūnan falabith'ta sinīna fī ahli madyana thumma ji'ta ʿalā qadarin yāmūsā

Yoruba (Rántí) nígbà tí arábìnrin rẹ ń rìn lọ, ó sì ń sọ pé: “Ṣé kí n̄g júwe yín sí ẹni tí ó máa gbà á tọ́?” A sì dá ọ padà sọ́dọ̀ ìyá rẹ nítorí kí ó lè ní ìtutù ojú, àti pé kí ò má baà banújẹ́. Àti pé o pa ẹ̀mí ẹnì kan. A sì mú ọ kúrò nínú ìbànújẹ́. A tún mú àwọn àdánwò kan bá ọ. O tún lo àwọn ọdún kan lọ́dọ̀ àwọn ará Mọdyan. Lẹ́yìn náà, o dé (ní àkókò) tí ó ti wà nínú kádàrá, Mūsā.

Verse 41

وَٱصْطَنَعْتُكَ لِنَفْسِى

Transliteration wa-iṣ'ṭanaʿtuka linafsī

Yoruba Mo sì ṣà ọ́ lẹ́ṣà fún (iṣẹ́) Mi.

Verse 42

ٱذْهَبْ أَنتَ وَأَخُوكَ بِـَٔايَـٰتِى وَلَا تَنِيَا فِى ذِكْرِى

Transliteration idh'hab anta wa-akhūka biāyātī walā taniyā fī dhik'rī

Yoruba Lọ, ìwọ àti arákùnrin rẹ pẹ̀lú àwọn àmì (iṣẹ́ ìyanu) Mi. Kí ẹ sì má ṣe kọ́lẹ níbi ìrántí Mi.

Verse 43

ٱذْهَبَآ إِلَىٰ فِرْعَوْنَ إِنَّهُۥ طَغَىٰ

Transliteration idh'habā ilā fir'ʿawna innahu ṭaghā

Yoruba Ẹ lọ bá Fir‘aon. Dájúdájú ó ti tayọ ẹnu-ààlà.

Verse 44

فَقُولَا لَهُۥ قَوْلًا لَّيِّنًا لَّعَلَّهُۥ يَتَذَكَّرُ أَوْ يَخْشَىٰ

Transliteration faqūlā lahu qawlan layyinan laʿallahu yatadhakkaru aw yakhshā

Yoruba Ẹ sọ ọ̀rọ̀ ẹ̀lẹ̀ fún un. Ó ṣeé ṣe kí ó lo ìṣítí tàbí kí ó páyà (Mi).”

Verse 45

قَالَا رَبَّنَآ إِنَّنَا نَخَافُ أَن يَفْرُطَ عَلَيْنَآ أَوْ أَن يَطْغَىٰ

Transliteration qālā rabbanā innanā nakhāfu an yafruṭa ʿalaynā aw an yaṭghā

Yoruba Àwọn méjèèjì sọ pé: “Olúwa wa, dájúdájú àwa ń páyà pé ó má yára jẹ wá níyà tàbí pé ó má tayọ ẹnu-ààlà.”

Verse 46

قَالَ لَا تَخَافَآ ۖ إِنَّنِى مَعَكُمَآ أَسْمَعُ وَأَرَىٰ

Transliteration qāla lā takhāfā innanī maʿakumā asmaʿu wa-arā

Yoruba (Allāhu) sọ pé: “Ẹ má ṣe páyà. Dájúdájú Èmi wà pẹ̀lú ẹ̀yin méjèèjì; Mò ń gbọ (yín), Mo sì ń ri (yín).”1

Verse 47

فَأْتِيَاهُ فَقُولَآ إِنَّا رَسُولَا رَبِّكَ فَأَرْسِلْ مَعَنَا بَنِىٓ إِسْرَٰٓءِيلَ وَلَا تُعَذِّبْهُمْ ۖ قَدْ جِئْنَـٰكَ بِـَٔايَةٍ مِّن رَّبِّكَ ۖ وَٱلسَّلَـٰمُ عَلَىٰ مَنِ ٱتَّبَعَ ٱلْهُدَىٰٓ

Transliteration fatiyāhu faqūlā innā rasūlā rabbika fa-arsil maʿanā banī is'rāīla walā tuʿadhib'hum qad ji'nāka biāyatin min rabbika wal-salāmu ʿalā mani ittabaʿa l-hudā

Yoruba Nítorí náà, ẹ lọ bá a, kí ẹ sọ fún un pé: “Dájúdájú Òjíṣẹ́ Olúwa rẹ ni àwa méjèèjì. Nítorí náà, jẹ́ kí àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl máa bá wa lọ. Má ṣe fìyà jẹ wọ́n. Dájúdájú a ti mú àmì kan wá bá ọ láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ. Kí àlàáfíà sì máa bá ẹni tí ó bá tẹ̀lé ìmọ̀nà náà.

Verse 48

إِنَّا قَدْ أُوحِىَ إِلَيْنَآ أَنَّ ٱلْعَذَابَ عَلَىٰ مَن كَذَّبَ وَتَوَلَّىٰ

Transliteration innā qad ūḥiya ilaynā anna l-ʿadhāba ʿalā man kadhaba watawallā

Yoruba Dájúdájú wọ́n ti fi ìmísí ránṣẹ́ sí wa pé, dájúdájú ìyà ń bẹ fún ẹni tí ó bá pe òdodo ní irọ́, tí ó sì kẹ̀yìn sí i.”

Verse 49

قَالَ فَمَن رَّبُّكُمَا يَـٰمُوسَىٰ

Transliteration qāla faman rabbukumā yāmūsā

Yoruba (Fir‘aon) wí pé: “Ta ni Olúwa ẹ̀yin méjèèjì, Mūsā?”

Verse 50

قَالَ رَبُّنَا ٱلَّذِىٓ أَعْطَىٰ كُلَّ شَىْءٍ خَلْقَهُۥ ثُمَّ هَدَىٰ

Transliteration qāla rabbunā alladhī aʿṭā kulla shayin khalqahu thumma hadā

Yoruba (Ànábì Mūsā) sọ pé: “Olúwa wa ni Ẹni tí Ó fún gbogbo n̄ǹkan ní ìṣẹ̀dá rẹ̀.Lẹ́yìn náà, Ó tọ́ ọ sí ọ̀nà.”

Verse 51

قَالَ فَمَا بَالُ ٱلْقُرُونِ ٱلْأُولَىٰ

Transliteration qāla famā bālu l-qurūni l-ūlā

Yoruba (Fir‘aon) wí pé: “Kí ló mú àwọn ìran àkọ́kọ́ (tí wọn kò fi mọ̀nà)?”

Verse 52

قَالَ عِلْمُهَا عِندَ رَبِّى فِى كِتَـٰبٍ ۖ لَّا يَضِلُّ رَبِّى وَلَا يَنسَى

Transliteration qāla ʿil'muhā ʿinda rabbī fī kitābin lā yaḍillu rabbī walā yansā

Yoruba (Ànábì Mūsā) sọ pé: “Ìmọ̀ rẹ̀ wà nínú tírà kan lọ́dọ̀ Olúwa mi. Olúwa mi kò níí ṣàṣìṣe. Kò sì níí gbàgbé.

Verse 53

ٱلَّذِى جَعَلَ لَكُمُ ٱلْأَرْضَ مَهْدًا وَسَلَكَ لَكُمْ فِيهَا سُبُلًا وَأَنزَلَ مِنَ ٱلسَّمَآءِ مَآءً فَأَخْرَجْنَا بِهِۦٓ أَزْوَٰجًا مِّن نَّبَاتٍ شَتَّىٰ

Transliteration alladhī jaʿala lakumu l-arḍa mahdan wasalaka lakum fīhā subulan wa-anzala mina l-samāi māan fa-akhrajnā bihi azwājan min nabātin shattā

Yoruba (Òun ni) Ẹni tí Ó tẹ́ ilẹ̀ ní pẹrẹsẹ fún yín. Ó sì la àwọn ọ̀nà sínú rẹ̀ fún yín. Ó sì sọ omi kalẹ̀ láti sánmọ̀. A sì fi mú oríṣiríṣi jáde nínú àwọn irúgbìn ní ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀.

Verse 54

كُلُوا۟ وَٱرْعَوْا۟ أَنْعَـٰمَكُمْ ۗ إِنَّ فِى ذَٰلِكَ لَـَٔايَـٰتٍ لِّأُو۟لِى ٱلنُّهَىٰ

Transliteration kulū wa-ir'ʿaw anʿāmakum inna fī dhālika laāyātin li-ulī l-nuhā

Yoruba Ẹ jẹ, kí ẹ sì fi bọ́ àwọn ẹran-ọ̀sìn yín. Dájúdájú àwọn àmì wà nínú ìyẹn fún àwọn onílàákàyè.

Verse 55

۞ مِنْهَا خَلَقْنَـٰكُمْ وَفِيهَا نُعِيدُكُمْ وَمِنْهَا نُخْرِجُكُمْ تَارَةً أُخْرَىٰ

Transliteration min'hā khalaqnākum wafīhā nuʿīdukum wamin'hā nukh'rijukum tāratan ukh'rā

Yoruba Láti ara erùpẹ̀ ni A ti da yín. Inú rẹ̀ sì ni A óò da yín padà sí. Láti inú rẹ̀ sì ni A óò ti mu yín jáde padà nígbà mìíràn.”

Verse 56

وَلَقَدْ أَرَيْنَـٰهُ ءَايَـٰتِنَا كُلَّهَا فَكَذَّبَ وَأَبَىٰ

Transliteration walaqad araynāhu āyātinā kullahā fakadhaba wa-abā

Yoruba Dájúdájú A ti fi àwọn àmì Wa hàn án, gbogbo rẹ̀. Àmọ́ ó pè é ní irọ́. Ó sì kọ̀ jálẹ̀.

Verse 57

قَالَ أَجِئْتَنَا لِتُخْرِجَنَا مِنْ أَرْضِنَا بِسِحْرِكَ يَـٰمُوسَىٰ

Transliteration qāla aji'tanā litukh'rijanā min arḍinā bisiḥ'rika yāmūsā

Yoruba Ó wí pé: “Ṣé o wá bá wa nítorí kí o lè mú wa jáde kúrò lórí ilẹ̀ wa pẹ̀lú idán rẹ ni, Mūsā?

Verse 58

فَلَنَأْتِيَنَّكَ بِسِحْرٍ مِّثْلِهِۦ فَٱجْعَلْ بَيْنَنَا وَبَيْنَكَ مَوْعِدًا لَّا نُخْلِفُهُۥ نَحْنُ وَلَآ أَنتَ مَكَانًا سُوًى

Transliteration falanatiyannaka bisiḥ'rin mith'lihi fa-ij'ʿal baynanā wabaynaka mawʿidan lā nukh'lifuhu naḥnu walā anta makānan suwan

Yoruba Dájúdájú a máa mú idán irú rẹ̀ wá bá ọ. Nítorí náà, mú àyè àdéhùn ìpàdé láààrin àwa àti ìwọ, tí àwa àti ìwọ kò sì níí yapa rẹ̀, (kí ó jẹ́) àyè kan tí kò níí fì sọ́dọ̀ igun méjèèjì.”

Verse 59

قَالَ مَوْعِدُكُمْ يَوْمُ ٱلزِّينَةِ وَأَن يُحْشَرَ ٱلنَّاسُ ضُحًى

Transliteration qāla mawʿidukum yawmu l-zīnati wa-an yuḥ'shara l-nāsu ḍuḥan

Yoruba (Ànábì Mūsā) sọ pé: “Àkókò ìpàdé yín ni ọjọ́ Ọ̀ṣọ́ (ìyẹn, ọjọ́ ọdún). Kí wọ́n sì kó àwọn ènìyàn jọ ní ìyálẹ̀ta.”

Verse 60

فَتَوَلَّىٰ فِرْعَوْنُ فَجَمَعَ كَيْدَهُۥ ثُمَّ أَتَىٰ

Transliteration fatawallā fir'ʿawnu fajamaʿa kaydahu thumma atā

Yoruba Fir‘aon pẹ̀yìndà. Ó sì sa ète rẹ̀ jọ mọ́ra wọn. Lẹ́yìn náà, ó dé (síbẹ̀).

Verse 61

قَالَ لَهُم مُّوسَىٰ وَيْلَكُمْ لَا تَفْتَرُوا۟ عَلَى ٱللَّهِ كَذِبًا فَيُسْحِتَكُم بِعَذَابٍ ۖ وَقَدْ خَابَ مَنِ ٱفْتَرَىٰ

Transliteration qāla lahum mūsā waylakum lā taftarū ʿalā l-lahi kadhiban fayus'ḥitakum biʿadhābin waqad khāba mani if'tarā

Yoruba (Ànábì Mūsā) sọ pé: “Ègbé yín ò! Ẹ má ṣe dá àdápa irọ́ mọ́ Allāhu nítorí kí Ó má baà fi ìyà pa yín rẹ́. Àti pé dájúdájú ẹnikẹ́ni tí ó bá dá àdápa irọ́ (mọ́ Allāhu) ti pòfo.”

Verse 62

فَتَنَـٰزَعُوٓا۟ أَمْرَهُم بَيْنَهُمْ وَأَسَرُّوا۟ ٱلنَّجْوَىٰ

Transliteration fatanāzaʿū amrahum baynahum wa-asarrū l-najwā

Yoruba Wọ́n fọ̀rọ̀ jomi toro ọ̀rọ̀ láààrin ara wọn. Wọ́n sì tẹ̀ sọ̀rọ̀.

Verse 63

قَالُوٓا۟ إِنْ هَـٰذَٰنِ لَسَـٰحِرَٰنِ يُرِيدَانِ أَن يُخْرِجَاكُم مِّنْ أَرْضِكُم بِسِحْرِهِمَا وَيَذْهَبَا بِطَرِيقَتِكُمُ ٱلْمُثْلَىٰ

Transliteration qālū in hādhāni lasāḥirāni yurīdāni an yukh'rijākum min arḍikum bisiḥ'rihimā wayadhhabā biṭarīqatikumu l-muth'lā

Yoruba Wọ́n wí pé: “Dájúdájú àwọn méjèèjì yìí, òpìdán ni wọ́n o. Wọ́n fẹ́ mu yín jáde kúrò lórí ilẹ̀ yín pẹ̀lú idán wọn ni. Wọ́n sì (fẹ́) gba ojú ọ̀nà yín tó dára jùlọ mọ yín lọ́wọ́.

Verse 64

فَأَجْمِعُوا۟ كَيْدَكُمْ ثُمَّ ٱئْتُوا۟ صَفًّا ۚ وَقَدْ أَفْلَحَ ٱلْيَوْمَ مَنِ ٱسْتَعْلَىٰ

Transliteration fa-ajmiʿū kaydakum thumma i'tū ṣaffan waqad aflaḥa l-yawma mani is'taʿlā

Yoruba Nítorí náà, ẹ kó ète yín jọ papọ̀ mọ́ra wọn. Lẹ́yìn náà, kí ẹ tò wá ní ọ̀wọ̀ọ̀wọ́. Dájúdájú ẹni tí ó bá borí ní òní ti jèrè.”

Verse 65

قَالُوا۟ يَـٰمُوسَىٰٓ إِمَّآ أَن تُلْقِىَ وَإِمَّآ أَن نَّكُونَ أَوَّلَ مَنْ أَلْقَىٰ

Transliteration qālū yāmūsā immā an tul'qiya wa-immā an nakūna awwala man alqā

Yoruba (Àwọn òpìdán) wí pé: “Mūsā, ìwọ ni o máa kọ́kọ́ ju (ọ̀pá sílẹ̀ ni) tàbí àwa ni a óò kọ́kọ́ jù ú sílẹ̀.”

Verse 66

قَالَ بَلْ أَلْقُوا۟ ۖ فَإِذَا حِبَالُهُمْ وَعِصِيُّهُمْ يُخَيَّلُ إِلَيْهِ مِن سِحْرِهِمْ أَنَّهَا تَسْعَىٰ

Transliteration qāla bal alqū fa-idhā ḥibāluhum waʿiṣiyyuhum yukhayyalu ilayhi min siḥ'rihim annahā tasʿā

Yoruba (Mūsā) sọ pé: “Ẹ ju (tiyín) sílẹ̀ (ná).” Nígbà náà ni àwọn okùn wọn àti ọ̀pá wọn bá ń yíra padà lójú rẹ̀ nípasẹ̀ idán wọn, bí ẹni pé dájúdájú wọ́n ń sáré.

Verse 67

فَأَوْجَسَ فِى نَفْسِهِۦ خِيفَةً مُّوسَىٰ

Transliteration fa-awjasa fī nafsihi khīfatan mūsā

Yoruba Ìbẹ̀rù wọn sì mú (Ànábì) Mūsā.1

Verse 68

قُلْنَا لَا تَخَفْ إِنَّكَ أَنتَ ٱلْأَعْلَىٰ

Transliteration qul'nā lā takhaf innaka anta l-aʿlā

Yoruba A sọ pé: “Má ṣe páyà. Dájúdájú ìwọ, ìwọ lo máa lékè.

Verse 69

وَأَلْقِ مَا فِى يَمِينِكَ تَلْقَفْ مَا صَنَعُوٓا۟ ۖ إِنَّمَا صَنَعُوا۟ كَيْدُ سَـٰحِرٍ ۖ وَلَا يُفْلِحُ ٱلسَّاحِرُ حَيْثُ أَتَىٰ

Transliteration wa-alqi mā fī yamīnika talqaf mā ṣanaʿū innamā ṣanaʿū kaydu sāḥirin walā yuf'liḥu l-sāḥiru ḥaythu atā

Yoruba Ju ohun tí ń bẹ ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ sílẹ̀. Ó sì máa gbé ohun tí wọ́n ṣe kalẹ̀ mì káló. Dájúdájú ohun tí wọ́n ṣe kalẹ̀, ète òpìdán ni. Òpìdán kò sì níí jèrè ní ibikíbi tí ó bá dé.”

Verse 70

فَأُلْقِىَ ٱلسَّحَرَةُ سُجَّدًا قَالُوٓا۟ ءَامَنَّا بِرَبِّ هَـٰرُونَ وَمُوسَىٰ

Transliteration fa-ul'qiya l-saḥaratu sujjadan qālū āmannā birabbi hārūna wamūsā

Yoruba Nítorí náà, iṣẹ́ ìyanu (Ànábì Mūsā) mú àwọn òpìdán wó lulẹ̀, tí wọ́n forí kanlẹ̀ (fún Allāhu). Wọ́n wí pé: “A gbàgbọ́ nínú Olúwa Hārūn àti Mūsā.”

Verse 71

قَالَ ءَامَنتُمْ لَهُۥ قَبْلَ أَنْ ءَاذَنَ لَكُمْ ۖ إِنَّهُۥ لَكَبِيرُكُمُ ٱلَّذِى عَلَّمَكُمُ ٱلسِّحْرَ ۖ فَلَأُقَطِّعَنَّ أَيْدِيَكُمْ وَأَرْجُلَكُم مِّنْ خِلَـٰفٍ وَلَأُصَلِّبَنَّكُمْ فِى جُذُوعِ ٱلنَّخْلِ وَلَتَعْلَمُنَّ أَيُّنَآ أَشَدُّ عَذَابًا وَأَبْقَىٰ

Transliteration qāla āmantum lahu qabla an ādhana lakum innahu lakabīrukumu alladhī ʿallamakumu l-siḥ'ra fala-uqaṭṭiʿanna aydiyakum wa-arjulakum min khilāfin wala-uṣallibannakum fī judhūʿi l-nakhli walataʿlamunna ayyunā ashaddu ʿadhāban wa-abqā

Yoruba (Fir‘aon) wí pé: “Ṣé ẹ ti gbàfà fún un ṣíwájú kí èmi tó yọ̀ǹda fún yín? Dájúdájú òun ni àgbà yín tí ó kọ yín ní idán pípa. Nítorí náà, dájúdájú mo máa gé àwọn ọwọ́ yín àti ẹsẹ̀ yín ní ìpasípayọ. Dájúdájú mo tún máa kàn yín mọ́ àwọn igi dàbínù. Dájúdájú ẹ̀yin yóò mọ èwo nínú wa ni ìyà (rẹ̀) yóò le jùlọ, tí ó sì máa pẹ́ jùlọ.”

Verse 72

قَالُوا۟ لَن نُّؤْثِرَكَ عَلَىٰ مَا جَآءَنَا مِنَ ٱلْبَيِّنَـٰتِ وَٱلَّذِى فَطَرَنَا ۖ فَٱقْضِ مَآ أَنتَ قَاضٍ ۖ إِنَّمَا تَقْضِى هَـٰذِهِ ٱلْحَيَوٰةَ ٱلدُّنْيَآ

Transliteration qālū lan nu'thiraka ʿalā mā jāanā mina l-bayināti wa-alladhī faṭaranā fa-iq'ḍi mā anta qāḍin innamā taqḍī hādhihi l-ḥayata l-dun'yā

Yoruba (Àwọn òpìdán) sọ pé: “Àwa kò níí gbọ́lá fún ọ lórí ohun tí ó dé bá wa nínú àwọn ẹ̀rí tó dájú, (a kò sì níí gbọ́lá fún ọ lórí) Ẹni tí Ó pilẹ̀ ìṣẹ̀dá wa. Nítorí náà, dá ohun tí ó bá fẹ́ dá ní ẹjọ́. Ilé ayé yìí nìkan ni o ti lè dájọ́.

Verse 73

إِنَّآ ءَامَنَّا بِرَبِّنَا لِيَغْفِرَ لَنَا خَطَـٰيَـٰنَا وَمَآ أَكْرَهْتَنَا عَلَيْهِ مِنَ ٱلسِّحْرِ ۗ وَٱللَّهُ خَيْرٌ وَأَبْقَىٰٓ

Transliteration innā āmannā birabbinā liyaghfira lanā khaṭāyānā wamā akrahtanā ʿalayhi mina l-siḥ'ri wal-lahu khayrun wa-abqā

Yoruba Dájúdájú àwa gbàgbọ́ nínú Olúwa wa nítorí kí Ó lè ṣe àforíjìn àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa fún wa àti ohun tí o jẹ wá nípá ṣe nínú idán pípa. Allāhu lóore jùlọ, Ó sì máa wà títí láéláé.

Verse 74

إِنَّهُۥ مَن يَأْتِ رَبَّهُۥ مُجْرِمًا فَإِنَّ لَهُۥ جَهَنَّمَ لَا يَمُوتُ فِيهَا وَلَا يَحْيَىٰ

Transliteration innahu man yati rabbahu muj'riman fa-inna lahu jahannama lā yamūtu fīhā walā yaḥyā

Yoruba Dájúdájú ẹnikẹ́ni tí ó bá wá bá Olúwa rẹ̀ ní (ipò) ẹlẹ́ṣẹ̀, dájúdájú iná Jahanamọ ti wà fún un. Kò níí kú sínú rẹ̀, kò sì níí wà lààyè.

Verse 75

وَمَن يَأْتِهِۦ مُؤْمِنًا قَدْ عَمِلَ ٱلصَّـٰلِحَـٰتِ فَأُو۟لَـٰٓئِكَ لَهُمُ ٱلدَّرَجَـٰتُ ٱلْعُلَىٰ

Transliteration waman yatihi mu'minan qad ʿamila l-ṣāliḥāti fa-ulāika lahumu l-darajātu l-ʿulā

Yoruba Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì wá bá A (ní ipò) onígbàgbọ́ òdodo, tí ó sì ti ṣe àwọn iṣẹ́ rere, àwọn wọ̀nyẹn ni àwọn ipò gíga ń bẹ fún.

Verse 76

جَنَّـٰتُ عَدْنٍ تَجْرِى مِن تَحْتِهَا ٱلْأَنْهَـٰرُ خَـٰلِدِينَ فِيهَا ۚ وَذَٰلِكَ جَزَآءُ مَن تَزَكَّىٰ

Transliteration jannātu ʿadnin tajrī min taḥtihā l-anhāru khālidīna fīhā wadhālika jazāu man tazakkā

Yoruba (Ohun ni) àwọn Ọgbà ìdẹ̀ra gbére tí àwọn odò ń ṣàn ní ìsàlẹ̀ rẹ̀. Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀. Ìyẹn sì ni ẹ̀san fún ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣàfọ̀mọ́ (iṣẹ́ rẹ̀).”

Verse 77

وَلَقَدْ أَوْحَيْنَآ إِلَىٰ مُوسَىٰٓ أَنْ أَسْرِ بِعِبَادِى فَٱضْرِبْ لَهُمْ طَرِيقًا فِى ٱلْبَحْرِ يَبَسًا لَّا تَخَـٰفُ دَرَكًا وَلَا تَخْشَىٰ

Transliteration walaqad awḥaynā ilā mūsā an asri biʿibādī fa-iḍ'rib lahum ṭarīqan fī l-baḥri yabasan lā takhāfu darakan walā takhshā

Yoruba Àti pé dájúdájú A ti fi ìmísí ránṣẹ́ sí (Ànábì) Mūsā báyìí pé: “Mú àwọn ẹrúsìn Mi rìn ní òru. Fi (ọ̀pá rẹ) na omi fún wọn (kí ó di) ojú ọ̀nà gbígbẹ nínú omi òkun. Má ṣe bẹ̀rù àlébá, má sì ṣe páyà (ìtẹ̀rì sínú omi òkun).”

Verse 78

فَأَتْبَعَهُمْ فِرْعَوْنُ بِجُنُودِهِۦ فَغَشِيَهُم مِّنَ ٱلْيَمِّ مَا غَشِيَهُمْ

Transliteration fa-atbaʿahum fir'ʿawnu bijunūdihi faghashiyahum mina l-yami mā ghashiyahum

Yoruba Fir‘aon sì tẹ̀lé wọn pẹ̀lú àwọn ọmọ ogun rẹ̀. Ohun tí ó bò wọ́n mọ́lẹ̀ dáru nínú odò sì bò wọ́n mọ́lẹ̀ dáru.

Verse 79

وَأَضَلَّ فِرْعَوْنُ قَوْمَهُۥ وَمَا هَدَىٰ

Transliteration wa-aḍalla fir'ʿawnu qawmahu wamā hadā

Yoruba Fir‘aon ṣi àwọn ènìyàn rẹ̀ lọ́nà; òun (náà) kò sì mọ̀nà.

Verse 80

يَـٰبَنِىٓ إِسْرَٰٓءِيلَ قَدْ أَنجَيْنَـٰكُم مِّنْ عَدُوِّكُمْ وَوَٰعَدْنَـٰكُمْ جَانِبَ ٱلطُّورِ ٱلْأَيْمَنَ وَنَزَّلْنَا عَلَيْكُمُ ٱلْمَنَّ وَٱلسَّلْوَىٰ

Transliteration yābanī is'rāīla qad anjaynākum min ʿaduwwikum wawāʿadnākum jāniba l-ṭūri l-aymana wanazzalnā ʿalaykumu l-mana wal-salwā

Yoruba Ẹ̀yin ọmọ ’Isrọ̄’īl, dájúdájú A ti gbà yín là lọ́wọ́ ọ̀tá yín. A sì ṣe àdéhùn fún yín (pé kí Ànábì Mūsā wá, kí Á bá a sọ̀rọ̀ tààrà) ní ẹ̀gbẹ́ àpáta ní ọwọ́ ọ̀tún(Ànábì Mūsā láààrin àpáta àti àfonífojì2 ní ìwọ̀ òòrùn3). A sì sọ ohun mímu mọnu àti ohun jíjẹ salwā kalẹ̀ fún yín.4

Verse 81

كُلُوا۟ مِن طَيِّبَـٰتِ مَا رَزَقْنَـٰكُمْ وَلَا تَطْغَوْا۟ فِيهِ فَيَحِلَّ عَلَيْكُمْ غَضَبِى ۖ وَمَن يَحْلِلْ عَلَيْهِ غَضَبِى فَقَدْ هَوَىٰ

Transliteration kulū min ṭayyibāti mā razaqnākum walā taṭghaw fīhi fayaḥilla ʿalaykum ghaḍabī waman yaḥlil ʿalayhi ghaḍabī faqad hawā

Yoruba Ẹ jẹ nínú àwọn n̄ǹkan dáadáa tí A pa lésè fún yín. Ẹ má sì kọjá ẹnu ààlà nínú rẹ̀ nítorí kí ìbínú Mi má baà kò le yín lórí. Ẹnikẹ́ni tí ìbínú Mi bá sì kò lé lórí, dájúdájú ó ti jábọ́ (sínú ìparun).

Verse 82

وَإِنِّى لَغَفَّارٌ لِّمَن تَابَ وَءَامَنَ وَعَمِلَ صَـٰلِحًا ثُمَّ ٱهْتَدَىٰ

Transliteration wa-innī laghaffārun liman tāba waāmana waʿamila ṣāliḥan thumma ih'tadā

Yoruba Dájúdájú Èmi ni Aláforíjìn fún ẹnikẹ́ni tí ó bá ronú pìwàdà, tí ó gbàgbọ́ ní òdodo, tí ó sì ṣe iṣẹ́ rere, lẹ́yìn náà tí ó tún tẹ̀lé ìmọ̀nà.

Verse 83

۞ وَمَآ أَعْجَلَكَ عَن قَوْمِكَ يَـٰمُوسَىٰ

Transliteration wamā aʿjalaka ʿan qawmika yāmūsā

Yoruba Kí ni ó mú ọ kánjú ya àwọn ènìyàn rẹ sílẹ̀, Mūsā?

Verse 84

قَالَ هُمْ أُو۟لَآءِ عَلَىٰٓ أَثَرِى وَعَجِلْتُ إِلَيْكَ رَبِّ لِتَرْضَىٰ

Transliteration qāla hum ulāi ʿalā atharī waʿajil'tu ilayka rabbi litarḍā

Yoruba Ó sọ pé: “Àwọn nìwọ̀nyí tí wọ́n ń tọ orípa mi bọ̀ (lẹ́yìn mi). Èmi sì kánjú wá sọ́dọ̀ Rẹ nítorí kí O lè yọ́nú sí mi ni, Olúwa mi.”

Verse 85

قَالَ فَإِنَّا قَدْ فَتَنَّا قَوْمَكَ مِنۢ بَعْدِكَ وَأَضَلَّهُمُ ٱلسَّامِرِىُّ

Transliteration qāla fa-innā qad fatannā qawmaka min baʿdika wa-aḍallahumu l-sāmiriyu

Yoruba (Allāhu) sọ pé: “Dájúdájú Àwa ti dán ìjọ rẹ wò lẹ́yìn rẹ. Àti pé Sāmiriy ṣì wọ́n lọ́nà.”

Verse 86

فَرَجَعَ مُوسَىٰٓ إِلَىٰ قَوْمِهِۦ غَضْبَـٰنَ أَسِفًا ۚ قَالَ يَـٰقَوْمِ أَلَمْ يَعِدْكُمْ رَبُّكُمْ وَعْدًا حَسَنًا ۚ أَفَطَالَ عَلَيْكُمُ ٱلْعَهْدُ أَمْ أَرَدتُّمْ أَن يَحِلَّ عَلَيْكُمْ غَضَبٌ مِّن رَّبِّكُمْ فَأَخْلَفْتُم مَّوْعِدِى

Transliteration farajaʿa mūsā ilā qawmihi ghaḍbāna asifan qāla yāqawmi alam yaʿid'kum rabbukum waʿdan ḥasanan afaṭāla ʿalaykumu l-ʿahdu am aradttum an yaḥilla ʿalaykum ghaḍabun min rabbikum fa-akhlaftum mawʿidī

Yoruba (Ànábì) Mūsā sì padà sọ́dọ̀ ìjọ rẹ̀ pẹ̀lú ìbínú àti ìbànújẹ́. Ó sọ pé: “Ẹ̀yin ìjọ mi, ṣé Olúwa yín kò ti ba yín ṣe àdéhùn dáadáa ni? Ṣé àdéhùn ti pẹ́ jù lójú yín ni tàbí ẹ fẹ́ kí ìbínú kò le yín lórí láti ọ̀dọ̀ Olúwa yín ni ẹ fi yapa àdéhùn mi?”

Verse 87

قَالُوا۟ مَآ أَخْلَفْنَا مَوْعِدَكَ بِمَلْكِنَا وَلَـٰكِنَّا حُمِّلْنَآ أَوْزَارًا مِّن زِينَةِ ٱلْقَوْمِ فَقَذَفْنَـٰهَا فَكَذَٰلِكَ أَلْقَى ٱلسَّامِرِىُّ

Transliteration qālū mā akhlafnā mawʿidaka bimalkinā walākinnā ḥummil'nā awzāran min zīnati l-qawmi faqadhafnāhā fakadhālika alqā l-sāmiriyu

Yoruba Wọ́n wí pé: “Àwa kò fínnúfíndọ̀ yapa àdéhùn fúnra wa, ṣùgbọ́n wọ́n di ẹrù ọ̀ṣọ́ àwọn ènìyàn (Misrọ) rù wá lọ́rùn. A sì jù ú sínú iná (pẹ̀lú àṣẹ Sāmiriyy). Báyẹn náà sì ni Sāmiriyy ṣe ju tirẹ̀.”

Verse 88

فَأَخْرَجَ لَهُمْ عِجْلًا جَسَدًا لَّهُۥ خُوَارٌ فَقَالُوا۟ هَـٰذَآ إِلَـٰهُكُمْ وَإِلَـٰهُ مُوسَىٰ فَنَسِىَ

Transliteration fa-akhraja lahum ʿij'lan jasadan lahu khuwārun faqālū hādhā ilāhukum wa-ilāhu mūsā fanasiya

Yoruba Ó sì (fi mọ) ọmọ màálù ọ̀bọrọgidi kan jáde fún wọn, tó ń dún (bíi màálù). Wọ́n sì wí pé: “Èyí ni ọlọ́hun yín àti ọlọ́hun Mūsā. Àmọ́ ó ti gbàgbé (rẹ̀).”

Verse 89

أَفَلَا يَرَوْنَ أَلَّا يَرْجِعُ إِلَيْهِمْ قَوْلًا وَلَا يَمْلِكُ لَهُمْ ضَرًّا وَلَا نَفْعًا

Transliteration afalā yarawna allā yarjiʿu ilayhim qawlan walā yamliku lahum ḍarran walā nafʿan

Yoruba Ṣé wọn kò rí i pé kò lè dá èsì ọ̀rọ̀ kan padà fún wọn ni, kò sì ní agbára láti kó ìnira tàbí àǹfààní kan bá wọn!

Verse 90

وَلَقَدْ قَالَ لَهُمْ هَـٰرُونُ مِن قَبْلُ يَـٰقَوْمِ إِنَّمَا فُتِنتُم بِهِۦ ۖ وَإِنَّ رَبَّكُمُ ٱلرَّحْمَـٰنُ فَٱتَّبِعُونِى وَأَطِيعُوٓا۟ أَمْرِى

Transliteration walaqad qāla lahum hārūnu min qablu yāqawmi innamā futintum bihi wa-inna rabbakumu l-raḥmānu fa-ittabiʿūnī wa-aṭīʿū amrī

Yoruba Àti pé dájúdájú Hārūn ti sọ fún wọn ṣíwájú pé: “Ẹ̀yin ìjọ mi, wọ́n kàn fi ṣe àdánwò fún yín ni. Dájúdájú Olúwa yín ni Àjọkẹ́-ayé. Nítorí náà, ẹ tẹ̀lé mi. Kí ẹ sì tẹ̀lé àṣẹ mi.”

Verse 91

قَالُوا۟ لَن نَّبْرَحَ عَلَيْهِ عَـٰكِفِينَ حَتَّىٰ يَرْجِعَ إِلَيْنَا مُوسَىٰ

Transliteration qālū lan nabraḥa ʿalayhi ʿākifīna ḥattā yarjiʿa ilaynā mūsā

Yoruba Wọ́n wí pé: “A ò níí yé dúró sọ́dọ̀ rẹ̀ tí a óò máa jọ́sìn fún un títí (Ànábì) Mūsā yóò fi padà sọ́dọ̀ wa.”

Verse 92

قَالَ يَـٰهَـٰرُونُ مَا مَنَعَكَ إِذْ رَأَيْتَهُمْ ضَلُّوٓا۟

Transliteration qāla yāhārūnu mā manaʿaka idh ra-aytahum ḍallū

Yoruba (Ànábì) Mūsā sọ pé: “Hārūn, kí ni ó kọ̀ fún ọ nígbà tí o rí wọn tí wọ́n ṣìnà

Verse 93

أَلَّا تَتَّبِعَنِ ۖ أَفَعَصَيْتَ أَمْرِى

Transliteration allā tattabiʿani afaʿaṣayta amrī

Yoruba láti tọ̀ mí wá? Ṣé o yapa àṣẹ mi ni?”

Verse 94

قَالَ يَبْنَؤُمَّ لَا تَأْخُذْ بِلِحْيَتِى وَلَا بِرَأْسِىٓ ۖ إِنِّى خَشِيتُ أَن تَقُولَ فَرَّقْتَ بَيْنَ بَنِىٓ إِسْرَٰٓءِيلَ وَلَمْ تَرْقُبْ قَوْلِى

Transliteration qāla yabna-umma lā takhudh biliḥ'yatī walā birasī innī khashītu an taqūla farraqta bayna banī is'rāīla walam tarqub qawlī

Yoruba (Ànábì Hārūn) sọ pé: “Ọmọ ìyá mi, má ṣe fi irungbọ̀n mi mú mi, (má ṣe fi irun) orí mi mú mi. Dájúdájú èmi páyà pé ó máa sọ pé: 'O dá òpínyà sílẹ̀ láààrin àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl. O ò sì ṣọ́ ọ̀rọ̀ mi.'“

Verse 95

قَالَ فَمَا خَطْبُكَ يَـٰسَـٰمِرِىُّ

Transliteration qāla famā khaṭbuka yāsāmiriyyu

Yoruba (Ànábì Mūsā) sọ pé: “Kí ni ọ̀rọ̀ tìrẹ ti jẹ́, Sāmiriyy?”

Verse 96

قَالَ بَصُرْتُ بِمَا لَمْ يَبْصُرُوا۟ بِهِۦ فَقَبَضْتُ قَبْضَةً مِّنْ أَثَرِ ٱلرَّسُولِ فَنَبَذْتُهَا وَكَذَٰلِكَ سَوَّلَتْ لِى نَفْسِى

Transliteration qāla baṣur'tu bimā lam yabṣurū bihi faqabaḍtu qabḍatan min athari l-rasūli fanabadhtuhā wakadhālika sawwalat lī nafsī

Yoruba (Sāmiriyy) wí pé: “Mo rí ohun tí wọn kò rí. Mo sì bu ẹ̀kúnwọ́ kan níbi (erùpẹ̀) ojú ẹsẹ̀ (ẹṣin) Òjíṣẹ́ (ìyẹn, mọlāika Jibrīl). Mo sì dà á sílẹ̀ (láti fi mọ ère). Báyẹn ni ẹ̀mí mi ṣe (aburú) ní ọ̀ṣọ́ fún mi.”

Verse 97

قَالَ فَٱذْهَبْ فَإِنَّ لَكَ فِى ٱلْحَيَوٰةِ أَن تَقُولَ لَا مِسَاسَ ۖ وَإِنَّ لَكَ مَوْعِدًا لَّن تُخْلَفَهُۥ ۖ وَٱنظُرْ إِلَىٰٓ إِلَـٰهِكَ ٱلَّذِى ظَلْتَ عَلَيْهِ عَاكِفًا ۖ لَّنُحَرِّقَنَّهُۥ ثُمَّ لَنَنسِفَنَّهُۥ فِى ٱلْيَمِّ نَسْفًا

Transliteration qāla fa-idh'hab fa-inna laka fī l-ḥayati an taqūla lā misāsa wa-inna laka mawʿidan lan tukh'lafahu wa-unẓur ilā ilāhika alladhī ẓalta ʿalayhi ʿākifan lanuḥarriqannahu thumma lanansifannahu fī l-yami nasfan

Yoruba (Ànábì Mūsā) sọ pé: “Nítorí náà, máa lọ. Dájúdájú (ìjìyà) rẹ nílé ayé yìí ni kí o máa wí pé, “Má fi ara kàn mí”. Àti pé dájúdájú ọjọ́ ìyà kan ń bẹ fún ọ tí wọn kò níí gbé fò ọ́. Kí o sì wo ọlọ́hun rẹ, èyí tí o takú tì lọ́rùn tí ò ń bọ, dájúdájú a máa dáná sun ún. Lẹ́yìn náà, dájúdájú a máa ku eérú rẹ̀ dànù pátápátá sínú odò.

Verse 98

إِنَّمَآ إِلَـٰهُكُمُ ٱللَّهُ ٱلَّذِى لَآ إِلَـٰهَ إِلَّا هُوَ ۚ وَسِعَ كُلَّ شَىْءٍ عِلْمًا

Transliteration innamā ilāhukumu l-lahu alladhī lā ilāha illā huwa wasiʿa kulla shayin ʿil'man

Yoruba Ọlọ́hun yín ni Allāhu nìkan, ẹni tí kò sí ọlọ́hun kan tí a gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo àyàfi Òun. Ó fi ìmọ̀ gbòòrò ju gbogbo n̄ǹkan.

Verse 99

كَذَٰلِكَ نَقُصُّ عَلَيْكَ مِنْ أَنۢبَآءِ مَا قَدْ سَبَقَ ۚ وَقَدْ ءَاتَيْنَـٰكَ مِن لَّدُنَّا ذِكْرًا

Transliteration kadhālika naquṣṣu ʿalayka min anbāi mā qad sabaqa waqad ātaynāka min ladunnā dhik'ran

Yoruba Báyẹn ni A ṣe ń sọ ìtàn fún ọ nínú àwọn ìró tí ó ti ṣíwájú. Láti ọ̀dọ̀ Wa sì ni A kúkú ti fún ọ ní ìrántí (ìyẹn, al-Ƙur’ān).

Verse 100

مَّنْ أَعْرَضَ عَنْهُ فَإِنَّهُۥ يَحْمِلُ يَوْمَ ٱلْقِيَـٰمَةِ وِزْرًا

Transliteration man aʿraḍa ʿanhu fa-innahu yaḥmilu yawma l-qiyāmati wiz'ran

Yoruba Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbúnrí kúrò níbẹ̀, dájúdájú ó máa ru ẹrù ẹ̀ṣẹ̀ ní Ọjọ́ Àjíǹde.

Verse 101

خَـٰلِدِينَ فِيهِ ۖ وَسَآءَ لَهُمْ يَوْمَ ٱلْقِيَـٰمَةِ حِمْلًا

Transliteration khālidīna fīhi wasāa lahum yawma l-qiyāmati ḥim'lan

Yoruba Olùṣegbére ni wọ́n nínú (ìyà) rẹ̀. (Ẹrù ẹ̀ṣẹ̀) sì burú fún wọn láti rù ní Ọjọ́ Àjíǹde.

Verse 102

يَوْمَ يُنفَخُ فِى ٱلصُّورِ ۚ وَنَحْشُرُ ٱلْمُجْرِمِينَ يَوْمَئِذٍ زُرْقًا

Transliteration yawma yunfakhu fī l-ṣūri wanaḥshuru l-muj'rimīna yawma-idhin zur'qan

Yoruba Ní ọjọ́ tí wọ́n á fọn fèrè oníwo fún àjíǹde. A sí máa kó àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ jọ ní ọjọ́ yẹn, tí ojú wọn yó sì dúdú batakun.

Verse 103

يَتَخَـٰفَتُونَ بَيْنَهُمْ إِن لَّبِثْتُمْ إِلَّا عَشْرًا

Transliteration yatakhāfatūna baynahum in labith'tum illā ʿashran

Yoruba Wọn yó sì máa sọ̀rọ̀ ní jẹ́ẹ́jẹ́ láààrin ara wọn pé: “Ẹ̀yin kò gbé ilé ayé tayọ (ọjọ́) mẹ́wàá.”

Verse 104

نَّحْنُ أَعْلَمُ بِمَا يَقُولُونَ إِذْ يَقُولُ أَمْثَلُهُمْ طَرِيقَةً إِن لَّبِثْتُمْ إِلَّا يَوْمًا

Transliteration naḥnu aʿlamu bimā yaqūlūna idh yaqūlu amthaluhum ṭarīqatan in labith'tum illā yawman

Yoruba Àwa nímọ̀ jùlọ nípa ohun tí wọ́n ń wí nígbà tí ẹni tí ọpọlọ rẹ̀ pé jùlọ nínú wọn wí pé: “Ẹ kò gbé ilé ayé tayọ ọjọ́ kan.”

Verse 105

وَيَسْـَٔلُونَكَ عَنِ ٱلْجِبَالِ فَقُلْ يَنسِفُهَا رَبِّى نَسْفًا

Transliteration wayasalūnaka ʿani l-jibāli faqul yansifuhā rabbī nasfan

Yoruba Wọ́n ń bi ọ́ léèrè nípa àwọn àpáta. Sọ pé: “Olúwa mi yóò kù wọ́n dànù pátápátá.

Verse 106

فَيَذَرُهَا قَاعًا صَفْصَفًا

Transliteration fayadharuhā qāʿan ṣafṣafan

Yoruba Nígbà náà, Ó máa fi wọ́n sílẹ̀ ni pẹ̀tẹ́lẹ̀ gban̄sasa.

Verse 107

لَّا تَرَىٰ فِيهَا عِوَجًا وَلَآ أَمْتًا

Transliteration lā tarā fīhā ʿiwajan walā amtan

Yoruba O ò sì níí rí ọ̀gbun tàbí gelemọ kan nínú rẹ̀.

Verse 108

يَوْمَئِذٍ يَتَّبِعُونَ ٱلدَّاعِىَ لَا عِوَجَ لَهُۥ ۖ وَخَشَعَتِ ٱلْأَصْوَاتُ لِلرَّحْمَـٰنِ فَلَا تَسْمَعُ إِلَّا هَمْسًا

Transliteration yawma-idhin yattabiʿūna l-dāʿiya lā ʿiwaja lahu wakhashaʿati l-aṣwātu lilrraḥmāni falā tasmaʿu illā hamsan

Yoruba Ní ọjọ́ yẹn, àwọn ènìyàn yóò tẹ̀lé olùpèpè náà, kò níí sí yíyà kúrò lẹ́yìn rẹ̀. Àwọn ohùn yó sì palọ́lọ́ fún Àjọkẹ́-ayé. Nítorí náà, o ò níí gbọ́ ohùn kan bí kò ṣe gìrìgìrì ẹsẹ̀.

Verse 109

يَوْمَئِذٍ لَّا تَنفَعُ ٱلشَّفَـٰعَةُ إِلَّا مَنْ أَذِنَ لَهُ ٱلرَّحْمَـٰنُ وَرَضِىَ لَهُۥ قَوْلًا

Transliteration yawma-idhin lā tanfaʿu l-shafāʿatu illā man adhina lahu l-raḥmānu waraḍiya lahu qawlan

Yoruba Ní ọjọ́ yẹn, ìṣìpẹ̀ kò níí ṣe àǹfààní àfi ẹni tí Àjọkẹ́-ayé bá yọ̀ǹda fún, tí Ó sì yọ́nú sí ọ̀rọ̀ fún un.1

Verse 110

يَعْلَمُ مَا بَيْنَ أَيْدِيهِمْ وَمَا خَلْفَهُمْ وَلَا يُحِيطُونَ بِهِۦ عِلْمًا

Transliteration yaʿlamu mā bayna aydīhim wamā khalfahum walā yuḥīṭūna bihi ʿil'man

Yoruba (Allāhu) mọ ohun tí ń bẹ níwájú wọn àti ohun tí ń bẹ ní ẹ̀yìn wọn. Àwọn kò sì fi ìmọ̀ rọkiri ká Rẹ̀.

Verse 111

۞ وَعَنَتِ ٱلْوُجُوهُ لِلْحَىِّ ٱلْقَيُّومِ ۖ وَقَدْ خَابَ مَنْ حَمَلَ ظُلْمًا

Transliteration waʿanati l-wujūhu lil'ḥayyi l-qayūmi waqad khāba man ḥamala ẓul'man

Yoruba Àwọn ojú yó sì wólẹ̀ fún Alààyè, Alámòjúútó-ẹ̀dá. Dájúdájú ẹnikẹ́ni tí ó bá di àbòsí mẹ́rù ti pòfo.

Verse 112

وَمَن يَعْمَلْ مِنَ ٱلصَّـٰلِحَـٰتِ وَهُوَ مُؤْمِنٌ فَلَا يَخَافُ ظُلْمًا وَلَا هَضْمًا

Transliteration waman yaʿmal mina l-ṣāliḥāti wahuwa mu'minun falā yakhāfu ẓul'man walā haḍman

Yoruba Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe nínú àwọn iṣẹ́ rere, tí ó sì jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo, kí ó má ṣe páyà àbòsí tàbí ìrẹ́jẹ kan (láti ọ̀dọ̀ Allāhu).

Verse 113

وَكَذَٰلِكَ أَنزَلْنَـٰهُ قُرْءَانًا عَرَبِيًّا وَصَرَّفْنَا فِيهِ مِنَ ٱلْوَعِيدِ لَعَلَّهُمْ يَتَّقُونَ أَوْ يُحْدِثُ لَهُمْ ذِكْرًا

Transliteration wakadhālika anzalnāhu qur'ānan ʿarabiyyan waṣarrafnā fīhi mina l-waʿīdi laʿallahum yattaqūna aw yuḥ'dithu lahum dhik'ran

Yoruba Báyẹn ni A ṣe sọ (ìrántí) kalẹ̀ ní ohun kíké pẹ̀lú èdè Lárúbáwá. A sì ṣe àlàyé oníran-ànran ìlérí sínú rẹ̀ nítorí kí wọ́n lè ṣọ́ra (fún ìyà) tàbí nítorí kí ó lè jẹ́ ìrántí fún wọn.

Verse 114

فَتَعَـٰلَى ٱللَّهُ ٱلْمَلِكُ ٱلْحَقُّ ۗ وَلَا تَعْجَلْ بِٱلْقُرْءَانِ مِن قَبْلِ أَن يُقْضَىٰٓ إِلَيْكَ وَحْيُهُۥ ۖ وَقُل رَّبِّ زِدْنِى عِلْمًا

Transliteration fataʿālā l-lahu l-maliku l-ḥaqu walā taʿjal bil-qur'āni min qabli an yuq'ḍā ilayka waḥyuhu waqul rabbi zid'nī ʿil'man

Yoruba Nítorí náà, Allāhu Ọba Òdodo ga jùlọ. Má ṣe kánjú pẹ̀lú al-Ƙur’ān ṣíwájú kí wọ́n tó parí ìmísí rẹ̀ fún ọ. Kí o sì sọ pé: “Olúwa mi, ṣàlékún ìmọ̀ fún mi.”

Verse 115

وَلَقَدْ عَهِدْنَآ إِلَىٰٓ ءَادَمَ مِن قَبْلُ فَنَسِىَ وَلَمْ نَجِدْ لَهُۥ عَزْمًا

Transliteration walaqad ʿahid'nā ilā ādama min qablu fanasiya walam najid lahu ʿazman

Yoruba Dájúdájú A ṣe àdéhùn fún (Ànábì) Ādam ṣíwájú. Ṣùgbọ́n ó gbàgbé. A kò sì bá a pẹ̀lú ìpinnu ọkàn.

Verse 116

وَإِذْ قُلْنَا لِلْمَلَـٰٓئِكَةِ ٱسْجُدُوا۟ لِـَٔادَمَ فَسَجَدُوٓا۟ إِلَّآ إِبْلِيسَ أَبَىٰ

Transliteration wa-idh qul'nā lil'malāikati us'judū liādama fasajadū illā ib'līsa abā

Yoruba Nígbà tí A sọ fún àwọn mọlāika pé: “Ẹ forí kanlẹ̀ kí Ādam. Wọ́n sì forí kanlẹ̀ kí i àfi ’Iblīs, (tí) ó kọ̀.”

Verse 117

فَقُلْنَا يَـٰٓـَٔادَمُ إِنَّ هَـٰذَا عَدُوٌّ لَّكَ وَلِزَوْجِكَ فَلَا يُخْرِجَنَّكُمَا مِنَ ٱلْجَنَّةِ فَتَشْقَىٰٓ

Transliteration faqul'nā yāādamu inna hādhā ʿaduwwun laka walizawjika falā yukh'rijannakumā mina l-janati fatashqā

Yoruba Nítorí náà, A sọ pé: “Ādam, dájúdájú èyí ni ọ̀tá fún ìwọ àti ìyàwó rẹ. Nítorí náà, kò gbọdọ̀ mú ẹ̀yin méjèèjì jáde kúrò nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra nítorí kí o má baà máa dààmú (fún ìjẹ-ìmu).

Verse 118

إِنَّ لَكَ أَلَّا تَجُوعَ فِيهَا وَلَا تَعْرَىٰ

Transliteration inna laka allā tajūʿa fīhā walā taʿrā

Yoruba Dájúdájú ebi kò níí pa ọ́, o ò sì níí rìn hòhò nínú rẹ̀.

Verse 119

وَأَنَّكَ لَا تَظْمَؤُا۟ فِيهَا وَلَا تَضْحَىٰ

Transliteration wa-annaka lā taẓma-u fīhā walā taḍḥā

Yoruba Àti pé dájúdájú òǹgbẹ kò níí gbẹ ọ́ nínú rẹ̀, òòrùn kò sì níí pa ọ́.”

Verse 120

فَوَسْوَسَ إِلَيْهِ ٱلشَّيْطَـٰنُ قَالَ يَـٰٓـَٔادَمُ هَلْ أَدُلُّكَ عَلَىٰ شَجَرَةِ ٱلْخُلْدِ وَمُلْكٍ لَّا يَبْلَىٰ

Transliteration fawaswasa ilayhi l-shayṭānu qāla yāādamu hal adulluka ʿalā shajarati l-khul'di wamul'kin lā yablā

Yoruba Ṣùgbọ́n Èṣù kó ròyíròyí bá a; ó wí pé: “Ādam, ǹjẹ́ mo lè júwe rẹ sí igi gbére àti ìjọba tí kò níí tán?”

Verse 121

فَأَكَلَا مِنْهَا فَبَدَتْ لَهُمَا سَوْءَٰتُهُمَا وَطَفِقَا يَخْصِفَانِ عَلَيْهِمَا مِن وَرَقِ ٱلْجَنَّةِ ۚ وَعَصَىٰٓ ءَادَمُ رَبَّهُۥ فَغَوَىٰ

Transliteration fa-akalā min'hā fabadat lahumā sawātuhumā waṭafiqā yakhṣifāni ʿalayhimā min waraqi l-janati waʿaṣā ādamu rabbahu faghawā

Yoruba Nítorí náà, àwọn méjèèjì jẹ nínú (èso) rẹ̀. Ìhòhò àwọn méjèèjì sì hàn síra wọn; àwọn méjèèjì sì bẹ̀rẹ̀ sí da ewé Ọgbà Ìdẹ̀ra bo ara wọn. Ādam yapa àṣẹ Olúwa rẹ̀. Ó sì ṣìnà.

Verse 122

ثُمَّ ٱجْتَبَـٰهُ رَبُّهُۥ فَتَابَ عَلَيْهِ وَهَدَىٰ

Transliteration thumma ij'tabāhu rabbuhu fatāba ʿalayhi wahadā

Yoruba Lẹ́yìn náà, Olúwa rẹ̀ ṣà á lẹ́ṣà; Ó gba ìronúpìwàdà rẹ̀, Ó sì tọ́ ọ sí ọ̀nà.

Verse 123

قَالَ ٱهْبِطَا مِنْهَا جَمِيعًۢا ۖ بَعْضُكُمْ لِبَعْضٍ عَدُوٌّ ۖ فَإِمَّا يَأْتِيَنَّكُم مِّنِّى هُدًى فَمَنِ ٱتَّبَعَ هُدَاىَ فَلَا يَضِلُّ وَلَا يَشْقَىٰ

Transliteration qāla ih'biṭā min'hā jamīʿan baʿḍukum libaʿḍin ʿaduwwun fa-immā yatiyannakum minnī hudan famani ittabaʿa hudāya falā yaḍillu walā yashqā

Yoruba (Allāhu) sọ pé: “Ẹ̀yin méjèèjì, ẹ jáde kúrò nínú rẹ̀ pátápátá. Apá kan yín sì jẹ́ ọ̀tá sí apá kan - ẹ̀yin àti Èṣù. Nígbà tí ìmọ̀nà bá sì dé ba yín láti ọ̀dọ̀ Mi, ẹnikẹ́ni tí ó bá tẹ̀lé ìmọ̀nà Mi, kò níí ṣìnà, kò sì níí ṣorí burúkú.

Verse 124

وَمَنْ أَعْرَضَ عَن ذِكْرِى فَإِنَّ لَهُۥ مَعِيشَةً ضَنكًا وَنَحْشُرُهُۥ يَوْمَ ٱلْقِيَـٰمَةِ أَعْمَىٰ

Transliteration waman aʿraḍa ʿan dhik'rī fa-inna lahu maʿīshatan ḍankan wanaḥshuruhu yawma l-qiyāmati aʿmā

Yoruba Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì ṣẹ́rí kúrò níbi ìrántí Mi, dájúdájú ìṣẹ̀mí ìnira máa wà fún un. A sì máa gbé e dìde ní afọ́jú ní Ọjọ́ Àjíǹde.”

Verse 125

قَالَ رَبِّ لِمَ حَشَرْتَنِىٓ أَعْمَىٰ وَقَدْ كُنتُ بَصِيرًا

Transliteration qāla rabbi lima ḥashartanī aʿmā waqad kuntu baṣīran

Yoruba (Ó) máa wí pé: “Olúwa mi, nítorí kí ni O fi gbé mi dìde ní afọ́jú? Mo ti jẹ́ olùríran tẹ́lẹ̀!”

Verse 126

قَالَ كَذَٰلِكَ أَتَتْكَ ءَايَـٰتُنَا فَنَسِيتَهَا ۖ وَكَذَٰلِكَ ٱلْيَوْمَ تُنسَىٰ

Transliteration qāla kadhālika atatka āyātunā fanasītahā wakadhālika l-yawma tunsā

Yoruba (Allāhu) sọ pé: “Báyẹn ni àwọn āyah Wa ṣe dé bá ọ, o sì gbàgbé rẹ̀ (o pa á tì). Ní òní, báyẹn ni wọ́n ṣe máa gbàgbé ìwọ náà (sínú Iná).

Verse 127

وَكَذَٰلِكَ نَجْزِى مَنْ أَسْرَفَ وَلَمْ يُؤْمِنۢ بِـَٔايَـٰتِ رَبِّهِۦ ۚ وَلَعَذَابُ ٱلْـَٔاخِرَةِ أَشَدُّ وَأَبْقَىٰٓ

Transliteration wakadhālika najzī man asrafa walam yu'min biāyāti rabbihi walaʿadhābu l-ākhirati ashaddu wa-abqā

Yoruba Àti pé báyẹn ni A ṣe ń san ẹ̀san fún ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe àṣejù, tí kò sì gbàgbọ́ nínú àwọn āyah Olúwa rẹ̀. Dájúdájú ìyà Ọjọ́ Ìkẹ́yìn le jùlọ. Ó sì máa wà títí láéláé.”

Verse 128

أَفَلَمْ يَهْدِ لَهُمْ كَمْ أَهْلَكْنَا قَبْلَهُم مِّنَ ٱلْقُرُونِ يَمْشُونَ فِى مَسَـٰكِنِهِمْ ۗ إِنَّ فِى ذَٰلِكَ لَـَٔايَـٰتٍ لِّأُو۟لِى ٱلنُّهَىٰ

Transliteration afalam yahdi lahum kam ahlaknā qablahum mina l-qurūni yamshūna fī masākinihim inna fī dhālika laāyātin li-ulī l-nuhā

Yoruba Ṣé kò hàn sí wọn pé mélòó mélòó nínú àwọn ìran tí A ti parun ṣíwájú wọn, tí (àwọn wọ̀nyí náà) sì ń rìn kọjá ní ibùgbé wọn! Dájúdájú àwọn àmì wà nínú ìyẹn fún àwọn olóye.

Verse 129

وَلَوْلَا كَلِمَةٌ سَبَقَتْ مِن رَّبِّكَ لَكَانَ لِزَامًا وَأَجَلٌ مُّسَمًّى

Transliteration walawlā kalimatun sabaqat min rabbika lakāna lizāman wa-ajalun musamman

Yoruba Tí kò bá jẹ́ pé ọ̀rọ̀ kan tó ṣíwájú àti gbèdéke àkókò kan lọ́dọ̀ Olúwa rẹ (ìyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn) ìbá ti di dandan.

Verse 130

فَٱصْبِرْ عَلَىٰ مَا يَقُولُونَ وَسَبِّحْ بِحَمْدِ رَبِّكَ قَبْلَ طُلُوعِ ٱلشَّمْسِ وَقَبْلَ غُرُوبِهَا ۖ وَمِنْ ءَانَآئِ ٱلَّيْلِ فَسَبِّحْ وَأَطْرَافَ ٱلنَّهَارِ لَعَلَّكَ تَرْضَىٰ

Transliteration fa-iṣ'bir ʿalā mā yaqūlūna wasabbiḥ biḥamdi rabbika qabla ṭulūʿi l-shamsi waqabla ghurūbihā wamin ānāi al-layli fasabbiḥ wa-aṭrāfa l-nahāri laʿallaka tarḍā

Yoruba Nítorí náà, ṣe sùúrù lórí ohun tí wọ́n ń wí, kí o sì ṣe àfọ̀mọ́ pẹ̀lú ẹyìn fún Olúwa Rẹ ṣíwájú yíyọ òòrùn àti ṣíwájú wíwọ̀ rẹ̀. Ṣe àfọ̀mọ́ (fún Allāhu) ní àwọn àsìkò alẹ́ àti ní àwọn abala ọ̀sán nítorí kí (Á lè san ọ́ ní ẹ̀san rere tí) ó máa yọ́nú sí.

Verse 131

وَلَا تَمُدَّنَّ عَيْنَيْكَ إِلَىٰ مَا مَتَّعْنَا بِهِۦٓ أَزْوَٰجًا مِّنْهُمْ زَهْرَةَ ٱلْحَيَوٰةِ ٱلدُّنْيَا لِنَفْتِنَهُمْ فِيهِ ۚ وَرِزْقُ رَبِّكَ خَيْرٌ وَأَبْقَىٰ

Transliteration walā tamuddanna ʿaynayka ilā mā mattaʿnā bihi azwājan min'hum zahrata l-ḥayati l-dun'yā linaftinahum fīhi wariz'qu rabbika khayrun wa-abqā

Yoruba Má ṣe fẹjú rẹ sí ohun tí A fi ṣe ìgbádùn tó jẹ́ òdòdó ìṣẹ̀mí ilé ayé fún àwọn ìran-ìran kan nínú wọn. (A fún wọn) nítorí kí Á lè fi ṣe àdánwò fún wọn ni. Arísìkí Olúwa rẹ lóore jùlọ. Ó sì máa wà títí láéláé.

Verse 132

وَأْمُرْ أَهْلَكَ بِٱلصَّلَوٰةِ وَٱصْطَبِرْ عَلَيْهَا ۖ لَا نَسْـَٔلُكَ رِزْقًا ۖ نَّحْنُ نَرْزُقُكَ ۗ وَٱلْعَـٰقِبَةُ لِلتَّقْوَىٰ

Transliteration wamur ahlaka bil-ṣalati wa-iṣ'ṭabir ʿalayhā lā nasaluka riz'qan naḥnu narzuquka wal-ʿāqibatu lilttaqwā

Yoruba Pa ará ilé rẹ láṣẹ ìrun kíkí, kí o sì ṣe sùúrù lórí rẹ̀. A ò níí bèèrè èsè kan lọ́wọ́ rẹ; Àwa l’À ń pèsè fún ọ. Ìgbẹ̀yìn rere sì wà fún ìbẹ̀rù (Allāhu).

Verse 133

وَقَالُوا۟ لَوْلَا يَأْتِينَا بِـَٔايَةٍ مِّن رَّبِّهِۦٓ ۚ أَوَلَمْ تَأْتِهِم بَيِّنَةُ مَا فِى ٱلصُّحُفِ ٱلْأُولَىٰ

Transliteration waqālū lawlā yatīnā biāyatin min rabbihi awalam tatihim bayyinatu mā fī l-ṣuḥufi l-ūlā

Yoruba Wọ́n wí pé: “Nítorí kí ni kò fi mú àmì kan wá fún wa láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ̀?” Ṣé ẹ̀rí tó yanjú tó wà nínú àwọn tákàdá àkọ́kọ́ kò dé bá wọn ni?

Verse 134

وَلَوْ أَنَّآ أَهْلَكْنَـٰهُم بِعَذَابٍ مِّن قَبْلِهِۦ لَقَالُوا۟ رَبَّنَا لَوْلَآ أَرْسَلْتَ إِلَيْنَا رَسُولًا فَنَتَّبِعَ ءَايَـٰتِكَ مِن قَبْلِ أَن نَّذِلَّ وَنَخْزَىٰ

Transliteration walaw annā ahlaknāhum biʿadhābin min qablihi laqālū rabbanā lawlā arsalta ilaynā rasūlan fanattabiʿa āyātika min qabli an nadhilla wanakhzā

Yoruba Tí ó bá jẹ́ pé dájúdájú A ti fi ìyà kan pa wọ́n run ṣíwájú rẹ̀ ni, wọn ìbá wí pé: “Olúwa wa nítorí kí ni O ò ṣe rán Òjíṣẹ́ kan sí wa, àwa ìbá tẹ̀lé àwọn āyah Rẹ ṣíwájú kí á tó yẹpẹrẹ, (kí á sì tó) kàbùkù.”

Verse 135

قُلْ كُلٌّ مُّتَرَبِّصٌ فَتَرَبَّصُوا۟ ۖ فَسَتَعْلَمُونَ مَنْ أَصْحَـٰبُ ٱلصِّرَٰطِ ٱلسَّوِىِّ وَمَنِ ٱهْتَدَىٰ

Transliteration qul kullun mutarabbiṣun fatarabbaṣū fasataʿlamūna man aṣḥābu l-ṣirāṭi l-sawiyi wamani ih'tadā

Yoruba Sọ pé: “Ẹnì kọ̀ọ̀kan ni olùretí (ìkángun).” Nítorí náà, ẹ máa retí (rẹ̀). Ẹ máa mọ ta ni èrò ọ̀nà tààrà àti ẹni tó mọ̀nà.

Read Surah Taha in another language

All languages

All 114 surahs in Yoruba: the Qur’an in Yoruba.

Learn it in MyDugsi

Yoruba translation: Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni, from Quran.com. Transliteration: Quran.com. Recitation: Mishary Alafasy, from EveryAyah.com. MyDugsi is a learning aid, not a replacement for a qualified teacher.