Surah As-Sajdah in Yoruba: translation and audio
Surah 32 · السجدة · The Prostration · 30 verses
Surah As-Sajdah verse by verse: the Arabic with a recitation you can repeat, the transliteration, and the Yoruba translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni. For the meaning of every word, see Surah As-Sajdah word by word in English.
Verse 1
الٓمٓ
Transliteration alif-lam-meem
Yoruba ’Alif lām mīm. (Allāhu ló mọ ohun tí Ó gbàlérò pẹ̀lú àwọn háràfí náà.)1
Verse 2
تَنزِيلُ ٱلْكِتَـٰبِ لَا رَيْبَ فِيهِ مِن رَّبِّ ٱلْعَـٰلَمِينَ
Transliteration tanzīlu l-kitābi lā rayba fīhi min rabbi l-ʿālamīna
Yoruba Ìsọ̀kalẹ̀ Tírà náà, kò sí iyèméjì nínú rẹ̀ (pé ó wá) láti ọ̀dọ̀ Olúwa gbogbo ẹ̀dá.
Verse 3
أَمْ يَقُولُونَ ٱفْتَرَىٰهُ ۚ بَلْ هُوَ ٱلْحَقُّ مِن رَّبِّكَ لِتُنذِرَ قَوْمًا مَّآ أَتَىٰهُم مِّن نَّذِيرٍ مِّن قَبْلِكَ لَعَلَّهُمْ يَهْتَدُونَ
Transliteration am yaqūlūna if'tarāhu bal huwa l-ḥaqu min rabbika litundhira qawman mā atāhum min nadhīrin min qablika laʿallahum yahtadūna
Yoruba Tàbí wọ́n ń wí pé: “Ó dá àdápa irọ́ rẹ̀ ni.” Rárá o! Òdodo ni láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ nítorí kí o lè fi ṣèkìlọ̀ fún àwọn ènìyàn kan, tí olùkìlọ̀ kan kò wá bá wọn rí ṣíwájú rẹ, nítorí kí wọ́n lè mọ̀nà.1
Verse 4
ٱللَّهُ ٱلَّذِى خَلَقَ ٱلسَّمَـٰوَٰتِ وَٱلْأَرْضَ وَمَا بَيْنَهُمَا فِى سِتَّةِ أَيَّامٍ ثُمَّ ٱسْتَوَىٰ عَلَى ٱلْعَرْشِ ۖ مَا لَكُم مِّن دُونِهِۦ مِن وَلِىٍّ وَلَا شَفِيعٍ ۚ أَفَلَا تَتَذَكَّرُونَ
Transliteration al-lahu alladhī khalaqa l-samāwāti wal-arḍa wamā baynahumā fī sittati ayyāmin thumma is'tawā ʿalā l-ʿarshi mā lakum min dūnihi min waliyyin walā shafīʿin afalā tatadhakkarūna
Yoruba Allāhu ni Ẹni tí Ó ṣẹ̀dá àwọn sánmọ̀, ilẹ̀ àti n̄ǹkan tó wà láààrin méjèèjì láààrin ọjọ́ mẹ́fà. Lẹ́yìn náà, Ó gúnwà sórí Ìtẹ́-ọlá. Kò sí aláàbò àti olùṣìpẹ̀ kan fún yín lẹ́yìn Rẹ̀. Ṣé ẹ kò níí lo ìrántí ni?
Verse 5
يُدَبِّرُ ٱلْأَمْرَ مِنَ ٱلسَّمَآءِ إِلَى ٱلْأَرْضِ ثُمَّ يَعْرُجُ إِلَيْهِ فِى يَوْمٍ كَانَ مِقْدَارُهُۥٓ أَلْفَ سَنَةٍ مِّمَّا تَعُدُّونَ
Transliteration yudabbiru l-amra mina l-samāi ilā l-arḍi thumma yaʿruju ilayhi fī yawmin kāna miq'dāruhu alfa sanatin mimmā taʿuddūna
Yoruba Ó ń ṣètò ọ̀rọ̀ (ẹ̀dá) láti sánmọ̀ wá sórí ilẹ̀. Lẹ́yìn náà, (àbọ̀ ọ̀rọ̀ ẹ̀dá) yóò gùnkè tọ̀ Ọ́ lọ láààrin ọjọ́ kan tí òdiwọ̀n rẹ̀ tó ẹgbẹ̀rún ọdún nínú òǹkà tí ẹ̀ ń kà.1
Verse 6
ذَٰلِكَ عَـٰلِمُ ٱلْغَيْبِ وَٱلشَّهَـٰدَةِ ٱلْعَزِيزُ ٱلرَّحِيمُ
Transliteration dhālika ʿālimu l-ghaybi wal-shahādati l-ʿazīzu l-raḥīmu
Yoruba Ìyẹn ni Onímọ̀-ìkọ̀kọ̀ àti gban̄gba, Alágbára, Àṣàkẹ́-ọ̀run,
Verse 7
ٱلَّذِىٓ أَحْسَنَ كُلَّ شَىْءٍ خَلَقَهُۥ ۖ وَبَدَأَ خَلْقَ ٱلْإِنسَـٰنِ مِن طِينٍ
Transliteration alladhī aḥsana kulla shayin khalaqahu wabada-a khalqa l-insāni min ṭīnin
Yoruba Ẹni tó ṣe gbogbo n̄ǹkan tí Ó ṣẹ̀dá rẹ̀ ní dáadáa. Ó sì bẹ̀rẹ̀ ìṣẹ̀dá ènìyàn láti inú ẹrẹ̀.
Verse 8
ثُمَّ جَعَلَ نَسْلَهُۥ مِن سُلَـٰلَةٍ مِّن مَّآءٍ مَّهِينٍ
Transliteration thumma jaʿala naslahu min sulālatin min māin mahīnin
Yoruba Lẹ́yìn náà, Ó ṣe àwọn àrọ́mọdọ́mọ rẹ̀ láti ara ohun tí A mú jáde láti ara omi lílẹ yẹpẹrẹ.
Verse 9
ثُمَّ سَوَّىٰهُ وَنَفَخَ فِيهِ مِن رُّوحِهِۦ ۖ وَجَعَلَ لَكُمُ ٱلسَّمْعَ وَٱلْأَبْصَـٰرَ وَٱلْأَفْـِٔدَةَ ۚ قَلِيلًا مَّا تَشْكُرُونَ
Transliteration thumma sawwāhu wanafakha fīhi min rūḥihi wajaʿala lakumu l-samʿa wal-abṣāra wal-afidata qalīlan mā tashkurūna
Yoruba Lẹ́yìn náà, Ó to (oríkèéríkèé) rẹ̀ dọ́gba. Ó sì fẹ́ (ẹ̀mí) sí i lára nínú ẹ̀mí Rẹ̀ (tí Ó dá).Ó tún ṣe ìgbọ́rọ̀, ìríran àti ọkàn fún yín. Díẹ̀ ni ọpẹ́ tí ẹ̀ ń dá!
Verse 10
وَقَالُوٓا۟ أَءِذَا ضَلَلْنَا فِى ٱلْأَرْضِ أَءِنَّا لَفِى خَلْقٍ جَدِيدٍۭ ۚ بَلْ هُم بِلِقَآءِ رَبِّهِمْ كَـٰفِرُونَ
Transliteration waqālū a-idhā ḍalalnā fī l-arḍi a-innā lafī khalqin jadīdin bal hum biliqāi rabbihim kāfirūna
Yoruba Wọ́n sì wí pé: “Ǹjẹ́ nígbà tí a bá ti pòórá sínú ilẹ̀, ǹjẹ́ àwa tún lè wà ní ẹ̀dá titun mọ́? Àní sẹ́, àwọn ni aláìgbàgbọ́ nínú ìpàdé Olúwa wọn.
Verse 11
۞ قُلْ يَتَوَفَّىٰكُم مَّلَكُ ٱلْمَوْتِ ٱلَّذِى وُكِّلَ بِكُمْ ثُمَّ إِلَىٰ رَبِّكُمْ تُرْجَعُونَ
Transliteration qul yatawaffākum malaku l-mawti alladhī wukkila bikum thumma ilā rabbikum tur'jaʿūna
Yoruba Sọ pé: “Mọlāika ikú èyí tí A yàn fún yín máa gba ẹ̀mí yín. Lẹ́yìn náà, ọ̀dọ̀ Olúwa yín ni wọn máa da yín padà sí.”1
Verse 12
وَلَوْ تَرَىٰٓ إِذِ ٱلْمُجْرِمُونَ نَاكِسُوا۟ رُءُوسِهِمْ عِندَ رَبِّهِمْ رَبَّنَآ أَبْصَرْنَا وَسَمِعْنَا فَٱرْجِعْنَا نَعْمَلْ صَـٰلِحًا إِنَّا مُوقِنُونَ
Transliteration walaw tarā idhi l-muj'rimūna nākisū ruūsihim ʿinda rabbihim rabbanā abṣarnā wasamiʿ'nā fa-ir'jiʿ'nā naʿmal ṣāliḥan innā mūqinūna
Yoruba (Ìwọ ìbá rí èèmọ̀) tí ó bá jẹ́ pé o rí àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ nígbà tí wọ́n bá sorí kọ́ ní ọ̀dọ̀ Olúwa wọn, (wọ́n sì máa wí pé): “Olúwa wa, a ti ríran, a sì ti gbọ́ràn (báyìí), nítorí náà, dá wa padà (sí ilé ayé) nítorí kí á lè lọ ṣe iṣẹ́ rere; dájúdájú àwa ni alámọ̀dájú.”
Verse 13
وَلَوْ شِئْنَا لَـَٔاتَيْنَا كُلَّ نَفْسٍ هُدَىٰهَا وَلَـٰكِنْ حَقَّ ٱلْقَوْلُ مِنِّى لَأَمْلَأَنَّ جَهَنَّمَ مِنَ ٱلْجِنَّةِ وَٱلنَّاسِ أَجْمَعِينَ
Transliteration walaw shi'nā laātaynā kulla nafsin hudāhā walākin ḥaqqa l-qawlu minnī la-amla-anna jahannama mina l-jinati wal-nāsi ajmaʿīna
Yoruba Tí ó bá jẹ́ pé A bá fẹ́ ni, dájúdájú A ìbá fún gbogbo ẹ̀mí kọ̀ọ̀kan ní ìmọ̀nà rẹ̀, ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ náà ti ṣẹ láti ọ̀dọ̀ Mi (báyìí pé): “Dájúdájú Mo máa mú nínú àwọn àlùjànnú àti ènìyàn ní àpapọ̀ kún inú iná Jahanamọ.”
Verse 14
فَذُوقُوا۟ بِمَا نَسِيتُمْ لِقَآءَ يَوْمِكُمْ هَـٰذَآ إِنَّا نَسِينَـٰكُمْ ۖ وَذُوقُوا۟ عَذَابَ ٱلْخُلْدِ بِمَا كُنتُمْ تَعْمَلُونَ
Transliteration fadhūqū bimā nasītum liqāa yawmikum hādhā innā nasīnākum wadhūqū ʿadhāba l-khul'di bimā kuntum taʿmalūna
Yoruba Nítorí náà, ẹ tọ́ ìyà wò nítorí pé ẹ ti gbàgbé ìpàdé ọjọ́ yín (òní) yìí. Dájúdájú Àwa náà yóò gbàgbé yín (sínú Iná). Ẹ tọ́ ìyà gbére wò nítorí ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.1
Verse 15
إِنَّمَا يُؤْمِنُ بِـَٔايَـٰتِنَا ٱلَّذِينَ إِذَا ذُكِّرُوا۟ بِهَا خَرُّوا۟ سُجَّدًا وَسَبَّحُوا۟ بِحَمْدِ رَبِّهِمْ وَهُمْ لَا يَسْتَكْبِرُونَ ۩
Transliteration innamā yu'minu biāyātinā alladhīna idhā dhukkirū bihā kharrū sujjadan wasabbaḥū biḥamdi rabbihim wahum lā yastakbirūna
Yoruba Àwọn tó gbàgbọ́ nínú àwọn āyah Wa ni àwọn tí ó jẹ́ pé nígbà tí wọ́n bá fi ṣe ìṣítí fún wọn, wọn yóò dojú bolẹ̀ ní olùforíkanlẹ̀, wọn yó sì ṣe àfọ̀mọ́ pẹ̀lú ìdúpẹ́ fún Olúwa wọn. Wọn kò sì níí ṣègbéraga.
Verse 16
تَتَجَافَىٰ جُنُوبُهُمْ عَنِ ٱلْمَضَاجِعِ يَدْعُونَ رَبَّهُمْ خَوْفًا وَطَمَعًا وَمِمَّا رَزَقْنَـٰهُمْ يُنفِقُونَ
Transliteration tatajāfā junūbuhum ʿani l-maḍājiʿi yadʿūna rabbahum khawfan waṭamaʿan wamimmā razaqnāhum yunfiqūna
Yoruba Wọ́n ń gbé ẹ̀gbẹ́ wọn jìnnà sí ibùsùn. Wọ́n sì ń pe Olúwa wọn ní ti ìpáyà àti ìrètí. Wọ́n sì ń ná nínú ohun tí A pèsè fún wọn.
Verse 17
فَلَا تَعْلَمُ نَفْسٌ مَّآ أُخْفِىَ لَهُم مِّن قُرَّةِ أَعْيُنٍ جَزَآءًۢ بِمَا كَانُوا۟ يَعْمَلُونَ
Transliteration falā taʿlamu nafsun mā ukh'fiya lahum min qurrati aʿyunin jazāan bimā kānū yaʿmalūna
Yoruba Kò sí ẹ̀mí kan tí ó mọ ohun tí A fi pamọ́ fún wọn nínú àwọn n̄ǹkan ìtutù ojú. (Ó jẹ́) ẹ̀san ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́ (rere).
Verse 18
أَفَمَن كَانَ مُؤْمِنًا كَمَن كَانَ فَاسِقًا ۚ لَّا يَسْتَوُۥنَ
Transliteration afaman kāna mu'minan kaman kāna fāsiqan lā yastawūna
Yoruba Ǹjẹ́ ẹni tó jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo dà bí ẹni tó jẹ́ òbìlẹ̀jẹ́ bí? Wọn kò dọ́gba.
Verse 19
أَمَّا ٱلَّذِينَ ءَامَنُوا۟ وَعَمِلُوا۟ ٱلصَّـٰلِحَـٰتِ فَلَهُمْ جَنَّـٰتُ ٱلْمَأْوَىٰ نُزُلًۢا بِمَا كَانُوا۟ يَعْمَلُونَ
Transliteration ammā alladhīna āmanū waʿamilū l-ṣāliḥāti falahum jannātu l-mawā nuzulan bimā kānū yaʿmalūna
Yoruba Ní ti àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe iṣẹ́ rere, àwọn ibùgbé (nínú) Ọ̀gbà Ìdẹ̀ra ń bẹ fún wọn. (Ó jẹ́) ohun tí A pèsè sílẹ̀ (dè wọ́n) nítorí ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́ (rere).
Verse 20
وَأَمَّا ٱلَّذِينَ فَسَقُوا۟ فَمَأْوَىٰهُمُ ٱلنَّارُ ۖ كُلَّمَآ أَرَادُوٓا۟ أَن يَخْرُجُوا۟ مِنْهَآ أُعِيدُوا۟ فِيهَا وَقِيلَ لَهُمْ ذُوقُوا۟ عَذَابَ ٱلنَّارِ ٱلَّذِى كُنتُم بِهِۦ تُكَذِّبُونَ
Transliteration wa-ammā alladhīna fasaqū famawāhumu l-nāru kullamā arādū an yakhrujū min'hā uʿīdū fīhā waqīla lahum dhūqū ʿadhāba l-nāri alladhī kuntum bihi tukadhibūna
Yoruba Ní ti àwọn tó balẹ̀jẹ́, Iná ni ibùgbé wọn. Ìgbàkígbà tí wọ́n bá fẹ́ jáde kúrò nínú rẹ̀, A ó sì máa dá wọn padà sínú rẹ̀. A sì máa sọ fún wọn pé: “Ẹ tọ́ ìyà Iná tí ẹ̀ ń pè ní irọ́ wò.”1
Verse 21
وَلَنُذِيقَنَّهُم مِّنَ ٱلْعَذَابِ ٱلْأَدْنَىٰ دُونَ ٱلْعَذَابِ ٱلْأَكْبَرِ لَعَلَّهُمْ يَرْجِعُونَ
Transliteration walanudhīqannahum mina l-ʿadhābi l-adnā dūna l-ʿadhābi l-akbari laʿallahum yarjiʿūna
Yoruba Dájúdájú A máa fún wọn tọ́ wò nínú ìyà tó kéré jùlọ (nílé ayé) yàtọ̀ sí ìyà tó tóbi jùlọ (lọ́run) nítorí kí wọ́n lè ṣẹ́rí padà (síbi òdodo ṣíwájú ikú wọn).
Verse 22
وَمَنْ أَظْلَمُ مِمَّن ذُكِّرَ بِـَٔايَـٰتِ رَبِّهِۦ ثُمَّ أَعْرَضَ عَنْهَآ ۚ إِنَّا مِنَ ٱلْمُجْرِمِينَ مُنتَقِمُونَ
Transliteration waman aẓlamu mimman dhukkira biāyāti rabbihi thumma aʿraḍa ʿanhā innā mina l-muj'rimīna muntaqimūna
Yoruba Àti pé ta l’ó ṣe àbòsí tó tayọ ẹni tí wọn fi àwọn āyah Wa ṣe ìṣítí fún, lẹ́yìn náà, tí ó gbúnrí kúrò níbẹ̀? Dájúdájú Àwa máa gbẹ̀san lára àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀.
Verse 23
وَلَقَدْ ءَاتَيْنَا مُوسَى ٱلْكِتَـٰبَ فَلَا تَكُن فِى مِرْيَةٍ مِّن لِّقَآئِهِۦ ۖ وَجَعَلْنَـٰهُ هُدًى لِّبَنِىٓ إِسْرَٰٓءِيلَ
Transliteration walaqad ātaynā mūsā l-kitāba falā takun fī mir'yatin min liqāihi wajaʿalnāhu hudan libanī is'rāīla
Yoruba Dájúdájú A fún (Ànábì) Mūsā ní Tírà. Nítorí náà, má ṣe wà nínú iyèméjì nípa bí ó ṣe pàdé rẹ̀ (ìyẹn, nínú ìrìn-àjò òru àti gígun sánmọ̀).A sì ṣe Tírà A sì ṣe Tírà náà ní ìmọ̀nà fún àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl.
Verse 24
وَجَعَلْنَا مِنْهُمْ أَئِمَّةً يَهْدُونَ بِأَمْرِنَا لَمَّا صَبَرُوا۟ ۖ وَكَانُوا۟ بِـَٔايَـٰتِنَا يُوقِنُونَ
Transliteration wajaʿalnā min'hum a-immatan yahdūna bi-amrinā lammā ṣabarū wakānū biāyātinā yūqinūna
Yoruba Àti pé A ṣe àwọn kan nínú wọn ní Imām (aṣíwájú) tí wọ́n ń fi àṣẹ Wa (ohun tí A pa wọ́n ní àṣẹ rẹ̀ nínú at-Taorāh) tọ́ àwọn ènìyàn wọn sí ọ̀nà òdodo. (A ṣe wọ́n bẹ́ẹ̀) nígbà tí wọ́n ṣe sùúrù, tí wọ́n sì ní àmọ̀dájú nípa àwọn āyah Wa.
Verse 25
إِنَّ رَبَّكَ هُوَ يَفْصِلُ بَيْنَهُمْ يَوْمَ ٱلْقِيَـٰمَةِ فِيمَا كَانُوا۟ فِيهِ يَخْتَلِفُونَ
Transliteration inna rabbaka huwa yafṣilu baynahum yawma l-qiyāmati fīmā kānū fīhi yakhtalifūna
Yoruba Dájúdájú Olúwa rẹ, Ó máa ṣe ìdájọ́ láààrin wọn ní Ọjọ́ Àjíǹde nípa ohun tí wọ́n ń yapa-ẹnu lórí rẹ̀.
Verse 26
أَوَلَمْ يَهْدِ لَهُمْ كَمْ أَهْلَكْنَا مِن قَبْلِهِم مِّنَ ٱلْقُرُونِ يَمْشُونَ فِى مَسَـٰكِنِهِمْ ۚ إِنَّ فِى ذَٰلِكَ لَـَٔايَـٰتٍ ۖ أَفَلَا يَسْمَعُونَ
Transliteration awalam yahdi lahum kam ahlaknā min qablihim mina l-qurūni yamshūna fī masākinihim inna fī dhālika laāyātin afalā yasmaʿūna
Yoruba Ṣé kò fojú hàn sí wọn pé, mélòó mélòó nínú àwọn ìran tí A ti parẹ́ ṣíwájú wọn. Àwọn náà sì ń rìn kọjá nínú àwọn ibùgbé wọn! Dájúdájú àwọn àmì wà nínú ìyẹn. Nítorí náà, ṣé wọn kò níí tẹ́tí gbọ́rọ̀ (òdodo ni)?
Verse 27
أَوَلَمْ يَرَوْا۟ أَنَّا نَسُوقُ ٱلْمَآءَ إِلَى ٱلْأَرْضِ ٱلْجُرُزِ فَنُخْرِجُ بِهِۦ زَرْعًا تَأْكُلُ مِنْهُ أَنْعَـٰمُهُمْ وَأَنفُسُهُمْ ۖ أَفَلَا يُبْصِرُونَ
Transliteration awalam yaraw annā nasūqu l-māa ilā l-arḍi l-juruzi fanukh'riju bihi zarʿan takulu min'hu anʿāmuhum wa-anfusuhum afalā yub'ṣirūna
Yoruba Tàbí wọn kò rí i pé dájúdájú Àwa l’À ń wa omi òjò lọ sórí ilẹ̀ gbígbẹ, tí A sì ń fi mú irúgbìn jáde? Àwọn ẹran-ọ̀sìn wọn àti àwọn náà sì ń jẹ nínú rẹ̀. Nítorí náà, ṣé wọn kò ríran ni?
Verse 28
وَيَقُولُونَ مَتَىٰ هَـٰذَا ٱلْفَتْحُ إِن كُنتُمْ صَـٰدِقِينَ
Transliteration wayaqūlūna matā hādhā l-fatḥu in kuntum ṣādiqīna
Yoruba Wọ́n sì ń wí pé: “Ìgbà wo ni Ìdájọ́ yìí máa ṣẹlẹ̀ tí ẹ bá jẹ́ olódodo?”
Verse 29
قُلْ يَوْمَ ٱلْفَتْحِ لَا يَنفَعُ ٱلَّذِينَ كَفَرُوٓا۟ إِيمَـٰنُهُمْ وَلَا هُمْ يُنظَرُونَ
Transliteration qul yawma l-fatḥi lā yanfaʿu alladhīna kafarū īmānuhum walā hum yunẓarūna
Yoruba Sọ pé: “Ní Ọjọ́ Ìdájọ́, ìgbàgbọ́ tí àwọn ọ̀ṣẹbọ máa fẹ́ ní nígbà tí wọ́n bá fojú rí ìyà Iná kò níí ṣe wọ́n ní àǹfààní. A kò sì níí fún wọn ní ìsinmi (nínú Iná).”1
Verse 30
فَأَعْرِضْ عَنْهُمْ وَٱنتَظِرْ إِنَّهُم مُّنتَظِرُونَ
Transliteration fa-aʿriḍ ʿanhum wa-intaẓir innahum muntaẓirūna
Yoruba Nítorí náà, ṣẹ́rí kúrò lọ́dọ̀ wọn, kí o sì máa retí (Ọjọ́ Ìdájọ́). Dájúdájú àwọn náà ń retí (rẹ̀).
Read Surah As-Sajdah in another language
- English (word by word)
- Albanian
- Amazigh
- Amharic
- Assamese
- Azerbaijani
- Bambara
- Bangla
- Bosnian
- Bulgarian
- Chechen
- Chinese
- Czech
- Dari
- Dhivehi
- Dutch
- Finnish
- French
- German
- Gujarati
- Hausa
- Hebrew
- Hindi
- Indonesian
- Italian
- Japanese
- Kannada
- Kazakh
- Khmer
- Kinyarwanda
- Korean
- Kurdish
- Luganda
- Malay
- Malayalam
- Maranao
- Marathi
- Nepali
- Norwegian
- Oromo
- Pashto
- Persian
- Polish
- Portuguese
- Romanian
- Russian
- Sindhi
- Sinhala
- Somali
- Spanish
- Swahili
- Swedish
- Tagalog
- Tajik
- Tamil
- Tatar
- Telugu
- Thai
- Turkish
- Ukrainian
- Urdu
- Uyghur
- Uzbek
- Vietnamese
- Yao
All 114 surahs in Yoruba: the Qur’an in Yoruba.
Yoruba translation: Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni, from Quran.com. Transliteration: Quran.com. Recitation: Mishary Alafasy, from EveryAyah.com. MyDugsi is a learning aid, not a replacement for a qualified teacher.