MyDugsiStart learning

Surah Ar-Rahman in Yoruba: translation and audio

Surah 55 · الرحمن · The Beneficent · 78 verses

Surah Ar-Rahman verse by verse: the Arabic with a recitation you can repeat, the transliteration, and the Yoruba translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni. For the meaning of every word, see Surah Ar-Rahman word by word in English.

Verse 1

ٱلرَّحْمَـٰنُ

Transliteration al-raḥmānu

Yoruba Àjọkẹ́-ayé,

Verse 2

عَلَّمَ ٱلْقُرْءَانَ

Transliteration ʿallama l-qur'āna

Yoruba Ó fi ìmọ̀ al-Ƙur’ān mọ (ẹni tí Ó fẹ́).

Verse 3

خَلَقَ ٱلْإِنسَـٰنَ

Transliteration khalaqa l-insāna

Yoruba Ó ṣẹ̀dá ènìyàn.

Verse 4

عَلَّمَهُ ٱلْبَيَانَ

Transliteration ʿallamahu l-bayāna

Yoruba Ó sì fi àlàyé (ọ̀rọ̀ sísọ) mọ̀ ọ́n.

Verse 5

ٱلشَّمْسُ وَٱلْقَمَرُ بِحُسْبَانٍ

Transliteration al-shamsu wal-qamaru biḥus'bānin

Yoruba Òòrùn àti òṣùpá (ń rìn) fún ìṣírò (ọjọ́ ayé).

Verse 6

وَٱلنَّجْمُ وَٱلشَّجَرُ يَسْجُدَانِ

Transliteration wal-najmu wal-shajaru yasjudāni

Yoruba Àwọn ìtàkùn ilẹ̀ àti igi ń forí kanlẹ̀ (fún Allāhu).

Verse 7

وَٱلسَّمَآءَ رَفَعَهَا وَوَضَعَ ٱلْمِيزَانَ

Transliteration wal-samāa rafaʿahā wawaḍaʿa l-mīzāna

Yoruba Àti sánmọ̀, Allāhu gbé e sókè. Ó sì fi òṣùwọ̀n òfin déédé lélẹ̀ (fún ẹ̀dá)

Verse 8

أَلَّا تَطْغَوْا۟ فِى ٱلْمِيزَانِ

Transliteration allā taṭghaw fī l-mīzāni

Yoruba pé kí ẹ má ṣe tayọ ẹnu-ààlà níbi òṣùwọ̀n.

Verse 9

وَأَقِيمُوا۟ ٱلْوَزْنَ بِٱلْقِسْطِ وَلَا تُخْسِرُوا۟ ٱلْمِيزَانَ

Transliteration wa-aqīmū l-wazna bil-qis'ṭi walā tukh'sirū l-mīzāna

Yoruba Ẹ gbé òṣùwọ̀n náà dúró pẹ̀lú dọ́gbadọ́gba. Kí ẹ sì má ṣe dín òṣùwọ̀n kù.

Verse 10

وَٱلْأَرْضَ وَضَعَهَا لِلْأَنَامِ

Transliteration wal-arḍa waḍaʿahā lil'anāmi

Yoruba Ilẹ̀, (Allāhu) gbé e kalẹ̀ (sí abẹ́ sánmọ̀ fún àwọn ẹ̀dá.

Verse 11

فِيهَا فَـٰكِهَةٌ وَٱلنَّخْلُ ذَاتُ ٱلْأَكْمَامِ

Transliteration fīhā fākihatun wal-nakhlu dhātu l-akmāmi

Yoruba Èso àti dàbínù alápó wà lórí (ilẹ̀).

Verse 12

وَٱلْحَبُّ ذُو ٱلْعَصْفِ وَٱلرَّيْحَانُ

Transliteration wal-ḥabu dhū l-ʿaṣfi wal-rayḥānu

Yoruba Àti èso onípòpórò àti olóòórùn dídùn (wà lórí ilẹ̀).

Verse 13

فَبِأَىِّ ءَالَآءِ رَبِّكُمَا تُكَذِّبَانِ

Transliteration fabi-ayyi ālāi rabbikumā tukadhibāni

Yoruba Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè ní irọ́?

Verse 14

خَلَقَ ٱلْإِنسَـٰنَ مِن صَلْصَـٰلٍ كَٱلْفَخَّارِ

Transliteration khalaqa l-insāna min ṣalṣālin kal-fakhāri

Yoruba (Allāhu) ṣẹ̀dá ènìyàn láti ara amọ̀ gbígbẹ tó ń dún kokoko bí ìkòkò amọ̀.

Verse 15

وَخَلَقَ ٱلْجَآنَّ مِن مَّارِجٍ مِّن نَّارٍ

Transliteration wakhalaqa l-jāna min mārijin min nārin

Yoruba Ó sì ṣẹ̀dá àlùjànnú láti ara ahọ́n iná tí kò ní èéfín.

Verse 16

فَبِأَىِّ ءَالَآءِ رَبِّكُمَا تُكَذِّبَانِ

Transliteration fabi-ayyi ālāi rabbikumā tukadhibāni

Yoruba Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè ní irọ́?

Verse 17

رَبُّ ٱلْمَشْرِقَيْنِ وَرَبُّ ٱلْمَغْرِبَيْنِ

Transliteration rabbu l-mashriqayni warabbu l-maghribayni

Yoruba Olúwa ibùyọ òòrùn méjèèjì àti ibùwọ̀ òòrùn méjèèjì.1

Verse 18

فَبِأَىِّ ءَالَآءِ رَبِّكُمَا تُكَذِّبَانِ

Transliteration fabi-ayyi ālāi rabbikumā tukadhibāni

Yoruba Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè ní irọ́?

Verse 19

مَرَجَ ٱلْبَحْرَيْنِ يَلْتَقِيَانِ

Transliteration maraja l-baḥrayni yaltaqiyāni

Yoruba (Allāhu) mú odò méjì (odò oníyọ̀ àti odò aládùn) ṣàn pàdé ara wọn.

Verse 20

بَيْنَهُمَا بَرْزَخٌ لَّا يَبْغِيَانِ

Transliteration baynahumā barzakhun lā yabghiyāni

Yoruba Gàgá kan sì wà láààrin àwọn méjèèjì tí wọn kò sì lè tayọ ẹnu-ààlà (rẹ̀ láààrin ara wọn).

Verse 21

فَبِأَىِّ ءَالَآءِ رَبِّكُمَا تُكَذِّبَانِ

Transliteration fabi-ayyi ālāi rabbikumā tukadhibāni

Yoruba Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè ní irọ́?

Verse 22

يَخْرُجُ مِنْهُمَا ٱللُّؤْلُؤُ وَٱلْمَرْجَانُ

Transliteration yakhruju min'humā l-lu'lu-u wal-marjānu

Yoruba Òkúta oníyebíye àti ìlẹ̀kẹ̀ iyùn ń jáde nínú àwọn (odò) méjèèjì náà.

Verse 23

فَبِأَىِّ ءَالَآءِ رَبِّكُمَا تُكَذِّبَانِ

Transliteration fabi-ayyi ālāi rabbikumā tukadhibāni

Yoruba Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè ní irọ́?

Verse 24

وَلَهُ ٱلْجَوَارِ ٱلْمُنشَـَٔاتُ فِى ٱلْبَحْرِ كَٱلْأَعْلَـٰمِ

Transliteration walahu l-jawāri l-munshaātu fī l-baḥri kal-aʿlāmi

Yoruba Ti (Allāhu) ni àwọn ọkọ̀ ojú-omi gogoro tó ń rìn nínú agbami òdò (tí wọ́n dà) bí àpáta gíga.

Verse 25

فَبِأَىِّ ءَالَآءِ رَبِّكُمَا تُكَذِّبَانِ

Transliteration fabi-ayyi ālāi rabbikumā tukadhibāni

Yoruba Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè ní irọ́?

Verse 26

كُلُّ مَنْ عَلَيْهَا فَانٍ

Transliteration kullu man ʿalayhā fānin

Yoruba Gbogbo ẹni tó wà lórí ilẹ̀ máa tán.

Verse 27

وَيَبْقَىٰ وَجْهُ رَبِّكَ ذُو ٱلْجَلَـٰلِ وَٱلْإِكْرَامِ

Transliteration wayabqā wajhu rabbika dhū l-jalāli wal-ik'rāmi

Yoruba Ojú Olúwa rẹ, Atóbi, Alápọ̀n-ọ́nlé sì máa wà títí láéláé.

Verse 28

فَبِأَىِّ ءَالَآءِ رَبِّكُمَا تُكَذِّبَانِ

Transliteration fabi-ayyi ālāi rabbikumā tukadhibāni

Yoruba Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè ní irọ́?

Verse 29

يَسْـَٔلُهُۥ مَن فِى ٱلسَّمَـٰوَٰتِ وَٱلْأَرْضِ ۚ كُلَّ يَوْمٍ هُوَ فِى شَأْنٍ

Transliteration yasaluhu man fī l-samāwāti wal-arḍi kulla yawmin huwa fī shanin

Yoruba Àwọn tó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ ń bèèrè (n̄ǹkan) lọ́dọ̀ Rẹ̀; Ó sì wà lórí ìṣe lójoojúmọ́.

Verse 30

فَبِأَىِّ ءَالَآءِ رَبِّكُمَا تُكَذِّبَانِ

Transliteration fabi-ayyi ālāi rabbikumā tukadhibāni

Yoruba Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè ní irọ́?

Verse 31

سَنَفْرُغُ لَكُمْ أَيُّهَ ٱلثَّقَلَانِ

Transliteration sanafrughu lakum ayyuha l-thaqalāni

Yoruba A óò mú tiyín gbọ́ (lọ́jọ́ ẹ̀san), ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú.

Verse 32

فَبِأَىِّ ءَالَآءِ رَبِّكُمَا تُكَذِّبَانِ

Transliteration fabi-ayyi ālāi rabbikumā tukadhibāni

Yoruba Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè ní irọ́?

Verse 33

يَـٰمَعْشَرَ ٱلْجِنِّ وَٱلْإِنسِ إِنِ ٱسْتَطَعْتُمْ أَن تَنفُذُوا۟ مِنْ أَقْطَارِ ٱلسَّمَـٰوَٰتِ وَٱلْأَرْضِ فَٱنفُذُوا۟ ۚ لَا تَنفُذُونَ إِلَّا بِسُلْطَـٰنٍ

Transliteration yāmaʿshara l-jini wal-insi ini is'taṭaʿtum an tanfudhū min aqṭāri l-samāwāti wal-arḍi fa-unfudhū lā tanfudhūna illā bisul'ṭānin

Yoruba Ẹ̀yin àwùjọ àlùjànnú àti ènìyàn, tí ẹ bá lágbára láti sá jáde nínú àwọn agbègbè sánmọ̀ àti ilẹ̀, ẹ sá jáde. Ẹ kò lè sá jáde àfi pẹ̀lú agbára.

Verse 34

فَبِأَىِّ ءَالَآءِ رَبِّكُمَا تُكَذِّبَانِ

Transliteration fabi-ayyi ālāi rabbikumā tukadhibāni

Yoruba Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè ní irọ́?

Verse 35

يُرْسَلُ عَلَيْكُمَا شُوَاظٌ مِّن نَّارٍ وَنُحَاسٌ فَلَا تَنتَصِرَانِ

Transliteration yur'salu ʿalaykumā shuwāẓun min nārin wanuḥāsun falā tantaṣirāni

Yoruba Wọ́n máa ju ahọ́n iná àti èéfín (tàbí oje idẹ) iná lé ẹ̀yin méjèèjì lórí, ẹ̀yin méjèèjì kò sì níí lè ranra yín lọ́wọ́.

Verse 36

فَبِأَىِّ ءَالَآءِ رَبِّكُمَا تُكَذِّبَانِ

Transliteration fabi-ayyi ālāi rabbikumā tukadhibāni

Yoruba Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè ní irọ́?

Verse 37

فَإِذَا ٱنشَقَّتِ ٱلسَّمَآءُ فَكَانَتْ وَرْدَةً كَٱلدِّهَانِ

Transliteration fa-idhā inshaqqati l-samāu fakānat wardatan kal-dihāni

Yoruba Nítorí náà, nígbà tí sánmọ̀ bá fàya pẹ́rẹpẹ̀rẹ, ó sì máa pọ́n wá wẹ̀ bí epo pupa gbígbá.

Verse 38

فَبِأَىِّ ءَالَآءِ رَبِّكُمَا تُكَذِّبَانِ

Transliteration fabi-ayyi ālāi rabbikumā tukadhibāni

Yoruba Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè ní irọ́?

Verse 39

فَيَوْمَئِذٍ لَّا يُسْـَٔلُ عَن ذَنۢبِهِۦٓ إِنسٌ وَلَا جَآنٌّ

Transliteration fayawma-idhin lā yus'alu ʿan dhanbihi insun walā jānnun

Yoruba Nítorí náà, ní ọjọ́ yẹn Wọn kò níí bi ènìyàn àti àlùjànnú kan léèrè nípa ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀; (ó ti wà ní àkọsílẹ̀ ní ọ̀dọ̀ Wa).

Verse 40

فَبِأَىِّ ءَالَآءِ رَبِّكُمَا تُكَذِّبَانِ

Transliteration fabi-ayyi ālāi rabbikumā tukadhibāni

Yoruba Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè ní irọ́?

Verse 41

يُعْرَفُ ٱلْمُجْرِمُونَ بِسِيمَـٰهُمْ فَيُؤْخَذُ بِٱلنَّوَٰصِى وَٱلْأَقْدَامِ

Transliteration yuʿ'rafu l-muj'rimūna bisīmāhum fayu'khadhu bil-nawāṣī wal-aqdāmi

Yoruba Wọ́n máa dá àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ mọ̀ pẹ̀lú àmì ara wọn. Wọ́n sì máa fi àásó orí àti ẹsẹ̀ gbá wọn mú.

Verse 42

فَبِأَىِّ ءَالَآءِ رَبِّكُمَا تُكَذِّبَانِ

Transliteration fabi-ayyi ālāi rabbikumā tukadhibāni

Yoruba Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè ní irọ́?

Verse 43

هَـٰذِهِۦ جَهَنَّمُ ٱلَّتِى يُكَذِّبُ بِهَا ٱلْمُجْرِمُونَ

Transliteration hādhihi jahannamu allatī yukadhibu bihā l-muj'rimūna

Yoruba Èyí ni iná Jahanamọ tí àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ń pè ní irọ́.

Verse 44

يَطُوفُونَ بَيْنَهَا وَبَيْنَ حَمِيمٍ ءَانٍ

Transliteration yaṭūfūna baynahā wabayna ḥamīmin ānin

Yoruba Wọn yóò máa rìn lọ rìn bọ̀ láààrin Iná àti omi tó gbóná parí.1

Verse 45

فَبِأَىِّ ءَالَآءِ رَبِّكُمَا تُكَذِّبَانِ

Transliteration fabi-ayyi ālāi rabbikumā tukadhibāni

Yoruba Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè ní irọ́?

Verse 46

وَلِمَنْ خَافَ مَقَامَ رَبِّهِۦ جَنَّتَانِ

Transliteration waliman khāfa maqāma rabbihi jannatāni

Yoruba Ọgbà Ìdẹ̀ra méjì ń bẹ fún ẹni tó bá páyà ìdúró rẹ̀ níwájú Olúwa rẹ̀.

Verse 47

فَبِأَىِّ ءَالَآءِ رَبِّكُمَا تُكَذِّبَانِ

Transliteration fabi-ayyi ālāi rabbikumā tukadhibāni

Yoruba Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè ní irọ́?

Verse 48

ذَوَاتَآ أَفْنَانٍ

Transliteration dhawātā afnānin

Yoruba (Àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra méjèèjì ní) àwọn ẹ̀ka igi tó kún fún àwọn èso oríṣiríṣi.

Verse 49

فَبِأَىِّ ءَالَآءِ رَبِّكُمَا تُكَذِّبَانِ

Transliteration fabi-ayyi ālāi rabbikumā tukadhibāni

Yoruba Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè ní irọ́?

Verse 50

فِيهِمَا عَيْنَانِ تَجْرِيَانِ

Transliteration fīhimā ʿaynāni tajriyāni

Yoruba Odò méjì tó ń ṣàn wà nínú ọgbà méjèèjì.

Verse 51

فَبِأَىِّ ءَالَآءِ رَبِّكُمَا تُكَذِّبَانِ

Transliteration fabi-ayyi ālāi rabbikumā tukadhibāni

Yoruba Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè ní irọ́?

Verse 52

فِيهِمَا مِن كُلِّ فَـٰكِهَةٍ زَوْجَانِ

Transliteration fīhimā min kulli fākihatin zawjāni

Yoruba Oríṣi méjì méjì ni èso kọ̀ọ̀kan tó wà nínú ọgbà méjèèjì.1

Verse 53

فَبِأَىِّ ءَالَآءِ رَبِّكُمَا تُكَذِّبَانِ

Transliteration fabi-ayyi ālāi rabbikumā tukadhibāni

Yoruba Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè ní irọ́?

Verse 54

مُتَّكِـِٔينَ عَلَىٰ فُرُشٍۭ بَطَآئِنُهَا مِنْ إِسْتَبْرَقٍ ۚ وَجَنَى ٱلْجَنَّتَيْنِ دَانٍ

Transliteration muttakiīna ʿalā furushin baṭāinuhā min is'tabraqin wajanā l-janatayni dānin

Yoruba Wọn yóò rọ̀gbọ̀kú lórí ìtẹ́, tí àwọn ìtẹ́ inú rẹ̀ jẹ́ àrán tó nípọn. Àwọn èso ọgbà méjèèjì sì wà ní àrọ́wọ́tó.

Verse 55

فَبِأَىِّ ءَالَآءِ رَبِّكُمَا تُكَذِّبَانِ

Transliteration fabi-ayyi ālāi rabbikumā tukadhibāni

Yoruba Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè ní irọ́?

Verse 56

فِيهِنَّ قَـٰصِرَٰتُ ٱلطَّرْفِ لَمْ يَطْمِثْهُنَّ إِنسٌ قَبْلَهُمْ وَلَا جَآنٌّ

Transliteration fīhinna qāṣirātu l-ṭarfi lam yaṭmith'hunna insun qablahum walā jānnun

Yoruba Àwọn obìnrin tí kì í wo ọkùnrin mìíràn wà nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra. Ènìyàn àti àlùjànnú kan kò sì fọwọ́ kàn wọ́n rí ṣíwájú wọn.

Verse 57

فَبِأَىِّ ءَالَآءِ رَبِّكُمَا تُكَذِّبَانِ

Transliteration fabi-ayyi ālāi rabbikumā tukadhibāni

Yoruba Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè ní irọ́?

Verse 58

كَأَنَّهُنَّ ٱلْيَاقُوتُ وَٱلْمَرْجَانُ

Transliteration ka-annahunna l-yāqūtu wal-marjānu

Yoruba Wọ́n dà bíi ìlẹ̀kẹ̀ ṣẹ̀gi àti ìlẹ̀kẹ̀ iyùn (nípa ẹwà àti dídára wọn).

Verse 59

فَبِأَىِّ ءَالَآءِ رَبِّكُمَا تُكَذِّبَانِ

Transliteration fabi-ayyi ālāi rabbikumā tukadhibāni

Yoruba Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè ní irọ́?

Verse 60

هَلْ جَزَآءُ ٱلْإِحْسَـٰنِ إِلَّا ٱلْإِحْسَـٰنُ

Transliteration hal jazāu l-iḥ'sāni illā l-iḥ'sānu

Yoruba Ǹjẹ́ ẹ̀san mìíràn wà fún ṣíṣe rere bí kò ṣe (ẹ̀san) rere.

Verse 61

فَبِأَىِّ ءَالَآءِ رَبِّكُمَا تُكَذِّبَانِ

Transliteration fabi-ayyi ālāi rabbikumā tukadhibāni

Yoruba Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè ní irọ́?

Verse 62

وَمِن دُونِهِمَا جَنَّتَانِ

Transliteration wamin dūnihimā jannatāni

Yoruba Ọgbà Ìdẹ̀ra méjì kan tún ń bẹ yàtọ̀ sí méjì (àkọ́kọ́ yẹn).

Verse 63

فَبِأَىِّ ءَالَآءِ رَبِّكُمَا تُكَذِّبَانِ

Transliteration fabi-ayyi ālāi rabbikumā tukadhibāni

Yoruba Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè ní irọ́?

Verse 64

مُدْهَآمَّتَانِ

Transliteration mud'hāmmatāni

Yoruba Aláwọ̀ ewéko (ni Ọgbà méjèèjì náà).

Verse 65

فَبِأَىِّ ءَالَآءِ رَبِّكُمَا تُكَذِّبَانِ

Transliteration fabi-ayyi ālāi rabbikumā tukadhibāni

Yoruba Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè ní irọ́?

Verse 66

فِيهِمَا عَيْنَانِ نَضَّاخَتَانِ

Transliteration fīhimā ʿaynāni naḍḍākhatāni

Yoruba Àwọn odò méjì tó ń tú omi jáde láì dáwọ́ dúró wà (nínú ọgbà méjèèjì náà).

Verse 67

فَبِأَىِّ ءَالَآءِ رَبِّكُمَا تُكَذِّبَانِ

Transliteration fabi-ayyi ālāi rabbikumā tukadhibāni

Yoruba Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè ní irọ́?

Verse 68

فِيهِمَا فَـٰكِهَةٌ وَنَخْلٌ وَرُمَّانٌ

Transliteration fīhimā fākihatun wanakhlun warummānun

Yoruba Èso ìpanu, dàbínù àti èso rumọ̄n wà nínú ọgbà méjèèjì náà.

Verse 69

فَبِأَىِّ ءَالَآءِ رَبِّكُمَا تُكَذِّبَانِ

Transliteration fabi-ayyi ālāi rabbikumā tukadhibāni

Yoruba Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè ní irọ́?

Verse 70

فِيهِنَّ خَيْرَٰتٌ حِسَانٌ

Transliteration fīhinna khayrātun ḥisānun

Yoruba Àwọn obìnrin rere, arẹwà wà nínú àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra náà.

Verse 71

فَبِأَىِّ ءَالَآءِ رَبِّكُمَا تُكَذِّبَانِ

Transliteration fabi-ayyi ālāi rabbikumā tukadhibāni

Yoruba Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè ní irọ́?

Verse 72

حُورٌ مَّقْصُورَٰتٌ فِى ٱلْخِيَامِ

Transliteration ḥūrun maqṣūrātun fī l-khiyāmi

Yoruba Àwọn ẹlẹ́yinjú-ẹgẹ́ kan (ni wọ́n), tí A fi pamọ́ sínú ilé-ọ̀ṣọ́.

Verse 73

فَبِأَىِّ ءَالَآءِ رَبِّكُمَا تُكَذِّبَانِ

Transliteration fabi-ayyi ālāi rabbikumā tukadhibāni

Yoruba Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè ní irọ́?

Verse 74

لَمْ يَطْمِثْهُنَّ إِنسٌ قَبْلَهُمْ وَلَا جَآنٌّ

Transliteration lam yaṭmith'hunna insun qablahum walā jānnun

Yoruba Ènìyàn àti àlùjànnú kan kò fọwọ́ kàn wọ́n rí ṣíwájú wọn.

Verse 75

فَبِأَىِّ ءَالَآءِ رَبِّكُمَا تُكَذِّبَانِ

Transliteration fabi-ayyi ālāi rabbikumā tukadhibāni

Yoruba Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè ní irọ́?

Verse 76

مُتَّكِـِٔينَ عَلَىٰ رَفْرَفٍ خُضْرٍ وَعَبْقَرِىٍّ حِسَانٍ

Transliteration muttakiīna ʿalā rafrafin khuḍ'rin waʿabqariyyin ḥisānin

Yoruba Wọn yóò rọ̀gbọ̀kú lórí àwọn tìmùtìmù aláwọ̀ ewéko àti ìtẹ́ tó dára.

Verse 77

فَبِأَىِّ ءَالَآءِ رَبِّكُمَا تُكَذِّبَانِ

Transliteration fabi-ayyi ālāi rabbikumā tukadhibāni

Yoruba Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè ní irọ́?

Verse 78

تَبَـٰرَكَ ٱسْمُ رَبِّكَ ذِى ٱلْجَلَـٰلِ وَٱلْإِكْرَامِ

Transliteration tabāraka us'mu rabbika dhī l-jalāli wal-ik'rāmi

Yoruba Ìbùkún ni fún orúkọ Olúwa rẹ, Atóbi, Alápọ̀n-ọ́nlé.

Read Surah Ar-Rahman in another language

All languages

All 114 surahs in Yoruba: the Qur’an in Yoruba.

Learn it in MyDugsi

Yoruba translation: Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni, from Quran.com. Transliteration: Quran.com. Recitation: Mishary Alafasy, from EveryAyah.com. MyDugsi is a learning aid, not a replacement for a qualified teacher.