MyDugsiStart learning

Surah Al-Mulk in Yoruba: translation and audio

Surah 67 · الملك · The Sovereignty · 30 verses

Surah Al-Mulk verse by verse: the Arabic with a recitation you can repeat, the transliteration, and the Yoruba translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni. For the meaning of every word, see Surah Al-Mulk word by word in English.

Verse 1

تَبَـٰرَكَ ٱلَّذِى بِيَدِهِ ٱلْمُلْكُ وَهُوَ عَلَىٰ كُلِّ شَىْءٍ قَدِيرٌ

Transliteration tabāraka alladhī biyadihi l-mul'ku wahuwa ʿalā kulli shayin qadīrun

Yoruba Ìbùkún ni fún Ẹni tí gbogbo ìjọba wà ní Ọwọ́ Rẹ̀. Òun sì ni Alágbára lórí gbogbo n̄ǹkan.

Verse 2

ٱلَّذِى خَلَقَ ٱلْمَوْتَ وَٱلْحَيَوٰةَ لِيَبْلُوَكُمْ أَيُّكُمْ أَحْسَنُ عَمَلًا ۚ وَهُوَ ٱلْعَزِيزُ ٱلْغَفُورُ

Transliteration alladhī khalaqa l-mawta wal-ḥayata liyabluwakum ayyukum aḥsanu ʿamalan wahuwa l-ʿazīzu l-ghafūru

Yoruba Ẹni tí Ó dá ikú àti ìṣẹ̀mí nítorí kí ó lè dan yín wò; èwo nínú yín l’ó máa ṣe iṣẹ́ rere jùlọ. Òun sì ni Alágbára, Aláforíjìn.

Verse 3

ٱلَّذِى خَلَقَ سَبْعَ سَمَـٰوَٰتٍ طِبَاقًا ۖ مَّا تَرَىٰ فِى خَلْقِ ٱلرَّحْمَـٰنِ مِن تَفَـٰوُتٍ ۖ فَٱرْجِعِ ٱلْبَصَرَ هَلْ تَرَىٰ مِن فُطُورٍ

Transliteration alladhī khalaqa sabʿa samāwātin ṭibāqan mā tarā fī khalqi l-raḥmāni min tafāwutin fa-ir'jiʿi l-baṣara hal tarā min fuṭūrin

Yoruba Ẹni tí Ó dá àwọn sánmọ̀ méje ní ìpele ìpele. O ò lè rí àìgúnrégé kan lára ẹ̀dá Àjọkẹ́-ayé. Nítorí náà, wò ó padà, ǹjẹ́ o rí ojú sísán kan (lára sánmọ̀)?

Verse 4

ثُمَّ ٱرْجِعِ ٱلْبَصَرَ كَرَّتَيْنِ يَنقَلِبْ إِلَيْكَ ٱلْبَصَرُ خَاسِئًا وَهُوَ حَسِيرٌ

Transliteration thumma ir'jiʿi l-baṣara karratayni yanqalib ilayka l-baṣaru khāsi-an wahuwa ḥasīrun

Yoruba Lẹ́yìn náà, wò ó padà ní ẹ̀ẹ̀ mejì, kí ojú rẹ padà sí ọ̀dọ̀ rẹ pẹ̀lú ìyẹpẹrẹ. Ó sì máa káàárẹ̀.

Verse 5

وَلَقَدْ زَيَّنَّا ٱلسَّمَآءَ ٱلدُّنْيَا بِمَصَـٰبِيحَ وَجَعَلْنَـٰهَا رُجُومًا لِّلشَّيَـٰطِينِ ۖ وَأَعْتَدْنَا لَهُمْ عَذَابَ ٱلسَّعِيرِ

Transliteration walaqad zayyannā l-samāa l-dun'yā bimaṣābīḥa wajaʿalnāhā rujūman lilshayāṭīni wa-aʿtadnā lahum ʿadhāba l-saʿīri

Yoruba Dájúdájú A ti fi (àwọn ìràwọ̀ tó ń tànmọ́lẹ̀ bí) àtùpà ṣe sánmọ̀ ilé ayé ní ọ̀ṣọ́. A tún ṣe wọ́n ni ẹ̀ta-ìràwọ̀ tí wọ́n ń jù mọ́ àwọn èṣù. A sì pèsè ìyà Iná tó ń jó sílẹ̀ dè wọ́n.

Verse 6

وَلِلَّذِينَ كَفَرُوا۟ بِرَبِّهِمْ عَذَابُ جَهَنَّمَ ۖ وَبِئْسَ ٱلْمَصِيرُ

Transliteration walilladhīna kafarū birabbihim ʿadhābu jahannama wabi'sa l-maṣīru

Yoruba Ìyà iná Jahanamọ sì wà fún àwọn tó ṣàì gbàgbọ́. Ìkángun náà sì burú.

Verse 7

إِذَآ أُلْقُوا۟ فِيهَا سَمِعُوا۟ لَهَا شَهِيقًا وَهِىَ تَفُورُ

Transliteration idhā ul'qū fīhā samiʿū lahā shahīqan wahiya tafūru

Yoruba Nígbà tí wọ́n bá jù wọ́n sínú rẹ̀, wọn yóò máa gbọ́ kíkùn rẹ̀, tí ó sì máa ru sókè.

Verse 8

تَكَادُ تَمَيَّزُ مِنَ ٱلْغَيْظِ ۖ كُلَّمَآ أُلْقِىَ فِيهَا فَوْجٌ سَأَلَهُمْ خَزَنَتُهَآ أَلَمْ يَأْتِكُمْ نَذِيرٌ

Transliteration takādu tamayyazu mina l-ghayẓi kullamā ul'qiya fīhā fawjun sa-alahum khazanatuhā alam yatikum nadhīrun

Yoruba Iná máa fẹ́ẹ̀ pínra rẹ̀ láti ara ìbínú. Ìgbàkígbà tí wọ́n bá ju ìjọ kan sínú rẹ̀, àwọn ẹ̀ṣọ́ Iná yóò máa bi wọ́n léèrè pé: “Ǹjẹ́ olùkìlọ̀ kan kò wá ba yín bí?”

Verse 9

قَالُوا۟ بَلَىٰ قَدْ جَآءَنَا نَذِيرٌ فَكَذَّبْنَا وَقُلْنَا مَا نَزَّلَ ٱللَّهُ مِن شَىْءٍ إِنْ أَنتُمْ إِلَّا فِى ضَلَـٰلٍ كَبِيرٍ

Transliteration qālū balā qad jāanā nadhīrun fakadhabnā waqul'nā mā nazzala l-lahu min shayin in antum illā fī ḍalālin kabīrin

Yoruba Wọn yóò wí pé: “Bẹ́ẹ̀ ni, dájúdájú olùkìlọ̀ kan ti wá bá wa, ṣùgbọ́n a pè é ní òpùrọ́. A sì wí pé Allāhu kò sọ n̄ǹkan kan kalẹ̀. Kí ni ẹ̀yin bí kò ṣe pé ẹ wà nínú ìṣìnà tó tóbi.”

Verse 10

وَقَالُوا۟ لَوْ كُنَّا نَسْمَعُ أَوْ نَعْقِلُ مَا كُنَّا فِىٓ أَصْحَـٰبِ ٱلسَّعِيرِ

Transliteration waqālū law kunnā nasmaʿu aw naʿqilu mā kunnā fī aṣḥābi l-saʿīri

Yoruba Wọ́n tún wí pé: “Tí ó bá jẹ́ pé a gbọ́ràn ni tàbí pé a ṣe làákàyè ni, àwa kò níí wà nínú èrò inú Iná tó ń jó.”

Verse 11

فَٱعْتَرَفُوا۟ بِذَنۢبِهِمْ فَسُحْقًا لِّأَصْحَـٰبِ ٱلسَّعِيرِ

Transliteration fa-iʿ'tarafū bidhanbihim fasuḥ'qan li-aṣḥābi l-saʿīri

Yoruba Wọ́n sì jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Nítorí náà, ìjìnnà sí ìkẹ́ Allāhu yó wà fún àwọn èrò inú Iná tó ń jó.

Verse 12

إِنَّ ٱلَّذِينَ يَخْشَوْنَ رَبَّهُم بِٱلْغَيْبِ لَهُم مَّغْفِرَةٌ وَأَجْرٌ كَبِيرٌ

Transliteration inna alladhīna yakhshawna rabbahum bil-ghaybi lahum maghfiratun wa-ajrun kabīrun

Yoruba Dájúdájú àwọn tó ń páyà Olúwa wọn ní ìkọ̀kọ̀, àforíjìn àti ẹ̀san tó tóbi ń bẹ fún wọn.

Verse 13

وَأَسِرُّوا۟ قَوْلَكُمْ أَوِ ٱجْهَرُوا۟ بِهِۦٓ ۖ إِنَّهُۥ عَلِيمٌۢ بِذَاتِ ٱلصُّدُورِ

Transliteration wa-asirrū qawlakum awi ij'harū bihi innahu ʿalīmun bidhāti l-ṣudūri

Yoruba Ẹ wí ọ̀rọ̀ yín ní jẹ́ẹ́jẹ́ tàbí ẹ wí i sókè, dájúdájú Òun ni Onímọ̀ nípa ohun tó wà nínú àwọn igbá-àyà ẹ̀dá.

Verse 14

أَلَا يَعْلَمُ مَنْ خَلَقَ وَهُوَ ٱللَّطِيفُ ٱلْخَبِيرُ

Transliteration alā yaʿlamu man khalaqa wahuwa l-laṭīfu l-khabīru

Yoruba Ṣé kò mọ Ẹni tí Ó ṣẹ̀dá ni?Òun sì ni Aláàánú, Alámọ̀tán.

Verse 15

هُوَ ٱلَّذِى جَعَلَ لَكُمُ ٱلْأَرْضَ ذَلُولًا فَٱمْشُوا۟ فِى مَنَاكِبِهَا وَكُلُوا۟ مِن رِّزْقِهِۦ ۖ وَإِلَيْهِ ٱلنُّشُورُ

Transliteration huwa alladhī jaʿala lakumu l-arḍa dhalūlan fa-im'shū fī manākibihā wakulū min riz'qihi wa-ilayhi l-nushūru

Yoruba Òun ni Ẹni tí Ó rọ ilẹ̀ fún yín. Nítorí náà, ẹ rìn ní àwọn agbègbè rẹ̀ káàkiri, kí ẹ sì jẹ nínú arísìkí Rẹ̀. Ọ̀dọ̀ Rẹ̀ sì ni àjíǹde ẹ̀dá wà.

Verse 16

ءَأَمِنتُم مَّن فِى ٱلسَّمَآءِ أَن يَخْسِفَ بِكُمُ ٱلْأَرْضَ فَإِذَا هِىَ تَمُورُ

Transliteration a-amintum man fī l-samāi an yakhsifa bikumu l-arḍa fa-idhā hiya tamūru

Yoruba Ṣé ẹ fọkànbalẹ̀ sí Ẹni tí Ó wà ní (òkè) sánmọ̀ pé kò lè jẹ́ kí ilẹ̀ gbe yín mì? Nígbà náà, ilẹ̀ yó sì máa mì tìtì.

Verse 17

أَمْ أَمِنتُم مَّن فِى ٱلسَّمَآءِ أَن يُرْسِلَ عَلَيْكُمْ حَاصِبًا ۖ فَسَتَعْلَمُونَ كَيْفَ نَذِيرِ

Transliteration am amintum man fī l-samāi an yur'sila ʿalaykum ḥāṣiban fasataʿlamūna kayfa nadhīri

Yoruba Tàbí ẹ̀ fọkànbalẹ̀ sí Ẹni tí Ó wà ní (òkè) sánmọ̀ pé kò lè fi òkúta iná ránṣẹ́ si yín ni? Nígbà náà, ẹ sì máa mọ bí ìkìlọ̀ Mi ti rí.1

Verse 18

وَلَقَدْ كَذَّبَ ٱلَّذِينَ مِن قَبْلِهِمْ فَكَيْفَ كَانَ نَكِيرِ

Transliteration walaqad kadhaba alladhīna min qablihim fakayfa kāna nakīri

Yoruba Àwọn tó ṣíwájú wọn kúkú pe òdodo ní irọ́. Báwo sì ni bí Mo ṣe (fi ìyà) kọ (aburú fún wọn) ti rí!

Verse 19

أَوَلَمْ يَرَوْا۟ إِلَى ٱلطَّيْرِ فَوْقَهُمْ صَـٰٓفَّـٰتٍ وَيَقْبِضْنَ ۚ مَا يُمْسِكُهُنَّ إِلَّا ٱلرَّحْمَـٰنُ ۚ إِنَّهُۥ بِكُلِّ شَىْءٍۭ بَصِيرٌ

Transliteration awalam yaraw ilā l-ṭayri fawqahum ṣāffātin wayaqbiḍ'na mā yum'sikuhunna illā l-raḥmānu innahu bikulli shayin baṣīrun

Yoruba Ṣé wọn kò rí àwọn ẹyẹ tí ó wà ní òkè wọn, tí (wọ́n) ń na ìyẹ́ apá (wọn), tí wọ́n sì ń pa á mọ́ra? Kiní kan kò mú wọn dúró (sínú òfurufú) àfi Àjọkẹ́-ayé. Dájúdájú Òun sì ni Olùríran nípa gbogbo n̄ǹkan.

Verse 20

أَمَّنْ هَـٰذَا ٱلَّذِى هُوَ جُندٌ لَّكُمْ يَنصُرُكُم مِّن دُونِ ٱلرَّحْمَـٰنِ ۚ إِنِ ٱلْكَـٰفِرُونَ إِلَّا فِى غُرُورٍ

Transliteration amman hādhā alladhī huwa jundun lakum yanṣurukum min dūni l-raḥmāni ini l-kāfirūna illā fī ghurūrin

Yoruba Ta ni ẹni tí ó máa jẹ́ ọmọ ogun fún yín, tí ó máa ràn yín lọ́wọ́ lẹ́yìn Àjọkẹ́-ayé? (Nínú) kí ni àwọn aláìgbàgbọ́ wà bí kò ṣe nínú ẹ̀tàn.

Verse 21

أَمَّنْ هَـٰذَا ٱلَّذِى يَرْزُقُكُمْ إِنْ أَمْسَكَ رِزْقَهُۥ ۚ بَل لَّجُّوا۟ فِى عُتُوٍّ وَنُفُورٍ

Transliteration amman hādhā alladhī yarzuqukum in amsaka riz'qahu bal lajjū fī ʿutuwwin wanufūrin

Yoruba Ta ni ẹni tí ó máa pèsè fún yín tí Ó bá dá arísìkí Rẹ̀ dúró? Ńṣe ni wọ́n ń ṣorí kunkun sí i nínú ìgbéraga àti sísá fún òdodo.

Verse 22

أَفَمَن يَمْشِى مُكِبًّا عَلَىٰ وَجْهِهِۦٓ أَهْدَىٰٓ أَمَّن يَمْشِى سَوِيًّا عَلَىٰ صِرَٰطٍ مُّسْتَقِيمٍ

Transliteration afaman yamshī mukibban ʿalā wajhihi ahdā amman yamshī sawiyyan ʿalā ṣirāṭin mus'taqīmin

Yoruba Ǹjẹ́ ẹni tó ń rìn ní ìdojúbolẹ̀ l’ó mọ̀nà jùlọ ni tàbí ẹni tó ń rìn sàn án lójú ọ̀nà tààrà?

Verse 23

قُلْ هُوَ ٱلَّذِىٓ أَنشَأَكُمْ وَجَعَلَ لَكُمُ ٱلسَّمْعَ وَٱلْأَبْصَـٰرَ وَٱلْأَفْـِٔدَةَ ۖ قَلِيلًا مَّا تَشْكُرُونَ

Transliteration qul huwa alladhī ansha-akum wajaʿala lakumu l-samʿa wal-abṣāra wal-afidata qalīlan mā tashkurūna

Yoruba Sọ pé: “Òun ni Ẹni tí Ó ṣẹ̀dá yín. Ó sì ṣe ìgbọ́rọ̀, ìríran àti àwọn ọkàn fún yín. Ọpẹ́ tí ẹ̀ ń dá sì kéré púpọ̀.”

Verse 24

قُلْ هُوَ ٱلَّذِى ذَرَأَكُمْ فِى ٱلْأَرْضِ وَإِلَيْهِ تُحْشَرُونَ

Transliteration qul huwa alladhī dhara-akum fī l-arḍi wa-ilayhi tuḥ'sharūna

Yoruba Sọ pé: “Òun ni Ẹni tí Ó da yín sí orí ilẹ̀. Ọ̀dọ̀ Rẹ̀ sì ni wọn yóò ko yín jọ sí.”

Verse 25

وَيَقُولُونَ مَتَىٰ هَـٰذَا ٱلْوَعْدُ إِن كُنتُمْ صَـٰدِقِينَ

Transliteration wayaqūlūna matā hādhā l-waʿdu in kuntum ṣādiqīna

Yoruba Wọ́n ń wí pé: “Ìgbà wo ni àdéhùn yìí yóò ṣẹ tí ẹ bá jẹ́ olódodo?”

Verse 26

قُلْ إِنَّمَا ٱلْعِلْمُ عِندَ ٱللَّهِ وَإِنَّمَآ أَنَا۠ نَذِيرٌ مُّبِينٌ

Transliteration qul innamā l-ʿil'mu ʿinda l-lahi wa-innamā anā nadhīrun mubīnun

Yoruba Sọ pé: “Ọ̀dọ̀ Allāhu nìkan ni ìmọ̀ (nípa) rẹ̀ wà. Èmi kàn jẹ́ olùkìlọ̀ pọ́nńbélé ni.”

Verse 27

فَلَمَّا رَأَوْهُ زُلْفَةً سِيٓـَٔتْ وُجُوهُ ٱلَّذِينَ كَفَرُوا۟ وَقِيلَ هَـٰذَا ٱلَّذِى كُنتُم بِهِۦ تَدَّعُونَ

Transliteration falammā ra-awhu zul'fatan sīat wujūhu alladhīna kafarū waqīla hādhā alladhī kuntum bihi taddaʿūna

Yoruba Nígbà tí wọ́n bá rí i tó súnmọ́, ojú àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ yóò korò wá fún ìbànújẹ́. A ó sì sọ fún wọn pé: “Èyí ni ohun tí ẹ̀ ń pè.”

Verse 28

قُلْ أَرَءَيْتُمْ إِنْ أَهْلَكَنِىَ ٱللَّهُ وَمَن مَّعِىَ أَوْ رَحِمَنَا فَمَن يُجِيرُ ٱلْكَـٰفِرِينَ مِنْ عَذَابٍ أَلِيمٍ

Transliteration qul ara-aytum in ahlakaniya l-lahu waman maʿiya aw raḥimanā faman yujīru l-kāfirīna min ʿadhābin alīmin

Yoruba Sọ pé: “Ẹ sọ fún mi, tí Allāhu bá pa èmi àti àwọn tó wà pẹ̀lú mi rẹ́, tàbí tí Ó bá kẹ́ wa (ṣé ẹ lè dí I lọ́wọ́ ni?) Nítorí náà, ta ni ó máa gba àwọn aláìgbàgbọ́ là nínú ìyà ẹlẹ́ta-eléro?

Verse 29

قُلْ هُوَ ٱلرَّحْمَـٰنُ ءَامَنَّا بِهِۦ وَعَلَيْهِ تَوَكَّلْنَا ۖ فَسَتَعْلَمُونَ مَنْ هُوَ فِى ضَلَـٰلٍ مُّبِينٍ

Transliteration qul huwa l-raḥmānu āmannā bihi waʿalayhi tawakkalnā fasataʿlamūna man huwa fī ḍalālin mubīnin

Yoruba Sọ pé: “Òun ni Àjọkẹ́-ayé. Àwa gbà Á gbọ́. Òun sì la gbáralé. Láìpẹ́ ẹ máa mọ ta ni ó wà nínú ìṣìnà pọ́nńbélé.”

Verse 30

قُلْ أَرَءَيْتُمْ إِنْ أَصْبَحَ مَآؤُكُمْ غَوْرًا فَمَن يَأْتِيكُم بِمَآءٍ مَّعِينٍۭ

Transliteration qul ara-aytum in aṣbaḥa māukum ghawran faman yatīkum bimāin maʿīnin

Yoruba Sọ pé: “Ẹ sọ fún mi, tí omi yín bá gbẹ wá, ta ni ẹni tí ó máa mú omi tó ń ṣàn wá fún yín?”1

Read Surah Al-Mulk in another language

All languages

All 114 surahs in Yoruba: the Qur’an in Yoruba.

Learn it in MyDugsi

Yoruba translation: Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni, from Quran.com. Transliteration: Quran.com. Recitation: Mishary Alafasy, from EveryAyah.com. MyDugsi is a learning aid, not a replacement for a qualified teacher.