Surah Al-Insan in Yoruba: translation and audio
Surah 76 · الانسان · The Man · 31 verses
Surah Al-Insan verse by verse: the Arabic with a recitation you can repeat, the transliteration, and the Yoruba translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni. For the meaning of every word, see Surah Al-Insan word by word in English.
Verse 1
هَلْ أَتَىٰ عَلَى ٱلْإِنسَـٰنِ حِينٌ مِّنَ ٱلدَّهْرِ لَمْ يَكُن شَيْـًٔا مَّذْكُورًا
Transliteration hal atā ʿalā l-insāni ḥīnun mina l-dahri lam yakun shayan madhkūran
Yoruba Ṣebí àkókò kan nínú ìgbà ti ré kọjá lórí ènìyàn tí (ènìyàn) kò jẹ́ kiní kan tí wọ́n ń dárúkọ?
Verse 2
إِنَّا خَلَقْنَا ٱلْإِنسَـٰنَ مِن نُّطْفَةٍ أَمْشَاجٍ نَّبْتَلِيهِ فَجَعَلْنَـٰهُ سَمِيعًۢا بَصِيرًا
Transliteration innā khalaqnā l-insāna min nuṭ'fatin amshājin nabtalīhi fajaʿalnāhu samīʿan baṣīran
Yoruba Dájúdájú Àwa ṣẹ̀dá ènìyàn láti ara àtọ̀ tó ròpọ̀ mọ́ra wọn (láti ara ọkùnrin àti obìnrin), A sì máa dán an wò.A sì ṣe é ní olùgbọ́, olùríran.
Verse 3
إِنَّا هَدَيْنَـٰهُ ٱلسَّبِيلَ إِمَّا شَاكِرًا وَإِمَّا كَفُورًا
Transliteration innā hadaynāhu l-sabīla immā shākiran wa-immā kafūran
Yoruba Dájúdájú A fi ọ̀nà mọ̀ ọ́n; Ó lè jẹ́ olùdúpẹ́, ó sì lè jẹ́ aláìmoore.
Verse 4
إِنَّآ أَعْتَدْنَا لِلْكَـٰفِرِينَ سَلَـٰسِلَا۟ وَأَغْلَـٰلًا وَسَعِيرًا
Transliteration innā aʿtadnā lil'kāfirīna salāsilā wa-aghlālan wasaʿīran
Yoruba Dájúdájú Àwa pèsè àwọn ẹ̀wọ̀n, àjàgà àti Iná sílẹ̀ de àwọn aláìgbàgbọ́.
Verse 5
إِنَّ ٱلْأَبْرَارَ يَشْرَبُونَ مِن كَأْسٍ كَانَ مِزَاجُهَا كَافُورًا
Transliteration inna l-abrāra yashrabūna min kasin kāna mizājuhā kāfūran
Yoruba Dájúdájú àwọn ẹni rere, wọn yóò máa mu omi kan nínú ife. Ohun tí A pòpọ̀ mọ́ (omi náà) ni káfúrà.
Verse 6
عَيْنًا يَشْرَبُ بِهَا عِبَادُ ٱللَّهِ يُفَجِّرُونَهَا تَفْجِيرًا
Transliteration ʿaynan yashrabu bihā ʿibādu l-lahi yufajjirūnahā tafjīran
Yoruba Omi ìṣẹ́lẹ̀rú kan ni, tí àwọn ẹrúsìn Allāhu yóò máa mu, tí wọn yó sì máa mú un ṣàn jáde dáadáa (ní ibi tí wọ́n bá ti fẹ́ ẹ).
Verse 7
يُوفُونَ بِٱلنَّذْرِ وَيَخَافُونَ يَوْمًا كَانَ شَرُّهُۥ مُسْتَطِيرًا
Transliteration yūfūna bil-nadhri wayakhāfūna yawman kāna sharruhu mus'taṭīran
Yoruba Wọ́n ń mú ẹ̀jẹ́ wọn ṣẹ. Wọ́n sì ń páyà ọjọ́ kan, tí aburú rẹ̀ jẹ́ ohun tí ó máa fọ́nká gan-an.
Verse 8
وَيُطْعِمُونَ ٱلطَّعَامَ عَلَىٰ حُبِّهِۦ مِسْكِينًا وَيَتِيمًا وَأَسِيرًا
Transliteration wayuṭ'ʿimūna l-ṭaʿāma ʿalā ḥubbihi mis'kīnan wayatīman wa-asīran
Yoruba Tòhun ti bí wọ́n ṣe ní ìfẹ́ sí (ọrọ̀ tó), wọ́n ń fún mẹ̀kúnnù, ọmọ òrukàn àti ẹrú ní oúnjẹ jẹ.
Verse 9
إِنَّمَا نُطْعِمُكُمْ لِوَجْهِ ٱللَّهِ لَا نُرِيدُ مِنكُمْ جَزَآءً وَلَا شُكُورًا
Transliteration innamā nuṭ'ʿimukum liwajhi l-lahi lā nurīdu minkum jazāan walā shukūran
Yoruba (Wọ́n sì ń sọ pé:) “Nítorí Ojú rere Allāhu (nìkan) l’a fi ń fun yín ní oúnjẹ jẹ; àwa kò sì gbèrò ẹ̀san tàbí ìdúpẹ́ kan láti ọ̀dọ̀ yín.
Verse 10
إِنَّا نَخَافُ مِن رَّبِّنَا يَوْمًا عَبُوسًا قَمْطَرِيرًا
Transliteration innā nakhāfu min rabbinā yawman ʿabūsan qamṭarīran
Yoruba Dájúdájú àwa ń páyà ọjọ́ kan tí (ẹ̀dá yóò) fajú ro kókó ní ọ̀dọ̀ Olúwa wa.”
Verse 11
فَوَقَىٰهُمُ ٱللَّهُ شَرَّ ذَٰلِكَ ٱلْيَوْمِ وَلَقَّىٰهُمْ نَضْرَةً وَسُرُورًا
Transliteration fawaqāhumu l-lahu sharra dhālika l-yawmi walaqqāhum naḍratan wasurūran
Yoruba Nítorí náà, Allāhu yóò ṣọ́ wọn níbi aburú ọjọ́ yẹn. Ó sì máa fún wọn ni ìtutù ojú àti ìdùnnú.
Verse 12
وَجَزَىٰهُم بِمَا صَبَرُوا۟ جَنَّةً وَحَرِيرًا
Transliteration wajazāhum bimā ṣabarū jannatan waḥarīran
Yoruba Ó sì máa san wọ́n ní ẹ̀san Ọgbà Ìdẹ̀ra àti aṣọ àlàárì nítorí pé wọ́n ṣe sùúrù.
Verse 13
مُّتَّكِـِٔينَ فِيهَا عَلَى ٱلْأَرَآئِكِ ۖ لَا يَرَوْنَ فِيهَا شَمْسًا وَلَا زَمْهَرِيرًا
Transliteration muttakiīna fīhā ʿalā l-arāiki lā yarawna fīhā shamsan walā zamharīran
Yoruba Wọn yóò máa rọ̀gbọ̀kú sórí àwọn ibùsùn wọn. Wọn kò sì níí rí òòrùn tàbí òtútù.
Verse 14
وَدَانِيَةً عَلَيْهِمْ ظِلَـٰلُهَا وَذُلِّلَتْ قُطُوفُهَا تَذْلِيلًا
Transliteration wadāniyatan ʿalayhim ẓilāluhā wadhullilat quṭūfuhā tadhlīlan
Yoruba Àwọn ibòji (inú Ọgbà Ìdẹ̀ra) yóò súnmọ́ wọn. A sì máa mú àwọn esò ibẹ̀ súnmọ́ àrọ́wọ́tó wọn ní ti sísúnmọ́.
Verse 15
وَيُطَافُ عَلَيْهِم بِـَٔانِيَةٍ مِّن فِضَّةٍ وَأَكْوَابٍ كَانَتْ قَوَارِيرَا۠
Transliteration wayuṭāfu ʿalayhim biāniyatin min fiḍḍatin wa-akwābin kānat qawārīrā
Yoruba Àti pé wọn yóò máa gbé ife ìmumi ńlá tí wọ́n ṣe láti ara fàdákà àti àwọn ife ìmumi kékeré tí ó jẹ́ aláwo káà kiri ọ̀dọ̀ wọn.
Verse 16
قَوَارِيرَا۟ مِن فِضَّةٍ قَدَّرُوهَا تَقْدِيرًا
Transliteration qawārīrā min fiḍḍatin qaddarūhā taqdīran
Yoruba Ife aláwo tí wọ́n ṣe láti ara fàdákà ni (wọ́n). A sì ṣe wọ́n níwọ̀n- níwọ̀n (tí ó ṣe wẹ́kú ohun tí wọ́n fẹ́ mu).
Verse 17
وَيُسْقَوْنَ فِيهَا كَأْسًا كَانَ مِزَاجُهَا زَنجَبِيلًا
Transliteration wayus'qawna fīhā kasan kāna mizājuhā zanjabīlan
Yoruba Àti pé wọn yóò máa fún wọn ní ife ọtí kan mu nínú (Ọgbà Ìdẹ̀ra). Ohun tí A pòpọ̀ mọ́ (ọtí náà) ni atalẹ̀.
Verse 18
عَيْنًا فِيهَا تُسَمَّىٰ سَلْسَبِيلًا
Transliteration ʿaynan fīhā tusammā salsabīlan
Yoruba Nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra (wọn yóò tún máa mu) omi ìṣẹ́lẹ̀rú kan, tí À ń pè ní omi salsabīl.
Verse 19
۞ وَيَطُوفُ عَلَيْهِمْ وِلْدَٰنٌ مُّخَلَّدُونَ إِذَا رَأَيْتَهُمْ حَسِبْتَهُمْ لُؤْلُؤًا مَّنثُورًا
Transliteration wayaṭūfu ʿalayhim wil'dānun mukhalladūna idhā ra-aytahum ḥasib'tahum lu'lu-an manthūran
Yoruba Àwọn ọ̀dọ́kùnrin tí kò níí gbó yó sì máa lọ bọ̀ láààrin wọn. Nígbà tí ìwọ bá sì rí wọn, ìwọ yóò kà wọ́n kún òkúta olówó iyebíye tí wọ́n tàn kalẹ̀.
Verse 20
وَإِذَا رَأَيْتَ ثَمَّ رَأَيْتَ نَعِيمًا وَمُلْكًا كَبِيرًا
Transliteration wa-idhā ra-ayta thamma ra-ayta naʿīman wamul'kan kabīran
Yoruba Nígbà tí ìwọ bá sì wo ibẹ̀ yẹn (nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra), ìwọ yóò rí ìdẹ̀ra àti ọlá tó tóbi.
Verse 21
عَـٰلِيَهُمْ ثِيَابُ سُندُسٍ خُضْرٌ وَإِسْتَبْرَقٌ ۖ وَحُلُّوٓا۟ أَسَاوِرَ مِن فِضَّةٍ وَسَقَىٰهُمْ رَبُّهُمْ شَرَابًا طَهُورًا
Transliteration ʿāliyahum thiyābu sundusin khuḍ'run wa-is'tabraqun waḥullū asāwira min fiḍḍatin wasaqāhum rabbuhum sharāban ṭahūran
Yoruba Aṣọ àlàárì fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ aláwọ̀ ewéko àti aṣọ àlàárì tó nípọn máa wà lókè wọn (àti lára wọn). A sì máa fi ẹ̀gbà-ọwọ́ onífàdákà ṣe wọ́n ní ọ̀ṣọ́. Olúwa wọn yó sì fún wọn ní ohun mímu mímọ́ mu.
Verse 22
إِنَّ هَـٰذَا كَانَ لَكُمْ جَزَآءً وَكَانَ سَعْيُكُم مَّشْكُورًا
Transliteration inna hādhā kāna lakum jazāan wakāna saʿyukum mashkūran
Yoruba Dájúdájú èyí jẹ́ ẹ̀san fun yín. Wọ́n sì máa fi ẹ̀san rere àdìpèlé dúpẹ́ iṣẹ́ yín fun yín.
Verse 23
إِنَّا نَحْنُ نَزَّلْنَا عَلَيْكَ ٱلْقُرْءَانَ تَنزِيلًا
Transliteration innā naḥnu nazzalnā ʿalayka l-qur'āna tanzīlan
Yoruba Dájúdájú Àwa l’A sọ al-Ƙur’ān kalẹ̀ fún ọ díẹ̀ díẹ̀.1
Verse 24
فَٱصْبِرْ لِحُكْمِ رَبِّكَ وَلَا تُطِعْ مِنْهُمْ ءَاثِمًا أَوْ كَفُورًا
Transliteration fa-iṣ'bir liḥuk'mi rabbika walā tuṭiʿ min'hum āthiman aw kafūran
Yoruba Nítorí náà, ṣe sùúrù fún ìdájọ́ Olúwa rẹ. Má ṣe tẹ̀lé ẹlẹ́ṣẹ̀ tàbí aláìmoore kan nínú wọn.
Verse 25
وَٱذْكُرِ ٱسْمَ رَبِّكَ بُكْرَةً وَأَصِيلًا
Transliteration wa-udh'kuri is'ma rabbika buk'ratan wa-aṣīlan
Yoruba Rántí orúkọ Olúwa rẹ ní àárọ̀ àti ní ìrọ̀lẹ́.
Verse 26
وَمِنَ ٱلَّيْلِ فَٱسْجُدْ لَهُۥ وَسَبِّحْهُ لَيْلًا طَوِيلًا
Transliteration wamina al-layli fa-us'jud lahu wasabbiḥ'hu laylan ṭawīlan
Yoruba Àti ní òru, forí kanlẹ̀ fún Un. Kí o sì ṣàfọ̀mọ́ fún Un ní òru fún ìgbà pípẹ́.
Verse 27
إِنَّ هَـٰٓؤُلَآءِ يُحِبُّونَ ٱلْعَاجِلَةَ وَيَذَرُونَ وَرَآءَهُمْ يَوْمًا ثَقِيلًا
Transliteration inna hāulāi yuḥibbūna l-ʿājilata wayadharūna warāahum yawman thaqīlan
Yoruba Dájúdájú àwọn wọ̀nyí fẹ́ràn ayé. Wọ́n sì ń pa ọjọ́ tó wúwo tì sẹ́yìn wọn.
Verse 28
نَّحْنُ خَلَقْنَـٰهُمْ وَشَدَدْنَآ أَسْرَهُمْ ۖ وَإِذَا شِئْنَا بَدَّلْنَآ أَمْثَـٰلَهُمْ تَبْدِيلًا
Transliteration naḥnu khalaqnāhum washadadnā asrahum wa-idhā shi'nā baddalnā amthālahum tabdīlan
Yoruba Àwa l’A ṣẹ̀dá wọn. A sì ṣe ìṣẹ̀dá wọn dáradára. Nígbà tí A bá sì fẹ́, A óò fi irú wọn pààrọ̀ wọn ní ti ìpààrọ̀.
Verse 29
إِنَّ هَـٰذِهِۦ تَذْكِرَةٌ ۖ فَمَن شَآءَ ٱتَّخَذَ إِلَىٰ رَبِّهِۦ سَبِيلًا
Transliteration inna hādhihi tadhkiratun faman shāa ittakhadha ilā rabbihi sabīlan
Yoruba Dájúdájú èyí ni ìrántí. Nítorí náà, ẹni tí ó bá fẹ́ kí ó mú ojú ọ̀nà tọ̀ sí ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ̀.
Verse 30
وَمَا تَشَآءُونَ إِلَّآ أَن يَشَآءَ ٱللَّهُ ۚ إِنَّ ٱللَّهَ كَانَ عَلِيمًا حَكِيمًا
Transliteration wamā tashāūna illā an yashāa l-lahu inna l-laha kāna ʿalīman ḥakīman
Yoruba Ẹ̀yin kò sì níí fẹ́ (kiní kan) àfi tí Allāhu bá fẹ́. Dájúdájú Allāhu ń jẹ́ Onímọ̀, Ọlọ́gbọ́n.1
Verse 31
يُدْخِلُ مَن يَشَآءُ فِى رَحْمَتِهِۦ ۚ وَٱلظَّـٰلِمِينَ أَعَدَّ لَهُمْ عَذَابًا أَلِيمًۢا
Transliteration yud'khilu man yashāu fī raḥmatihi wal-ẓālimīna aʿadda lahum ʿadhāban alīman
Yoruba Ó máa fi ẹni tí ó bá fẹ́ sínú ìkẹ́ rẹ̀. (Ní ti) àwọn alábòsí, Ó sì pèsè ìyà ẹlẹ́ta-eléro sílẹ̀ dè wọ́n.
Read Surah Al-Insan in another language
- English (word by word)
- Albanian
- Amazigh
- Amharic
- Assamese
- Azerbaijani
- Bambara
- Bangla
- Bosnian
- Bulgarian
- Chechen
- Chinese
- Czech
- Dari
- Dhivehi
- Dutch
- Finnish
- French
- German
- Gujarati
- Hausa
- Hebrew
- Hindi
- Indonesian
- Italian
- Japanese
- Kannada
- Kazakh
- Khmer
- Kinyarwanda
- Korean
- Kurdish
- Luganda
- Malay
- Malayalam
- Maranao
- Marathi
- Nepali
- Norwegian
- Oromo
- Pashto
- Persian
- Polish
- Portuguese
- Romanian
- Russian
- Sindhi
- Sinhala
- Somali
- Spanish
- Swahili
- Swedish
- Tagalog
- Tajik
- Tamil
- Tatar
- Telugu
- Thai
- Turkish
- Ukrainian
- Urdu
- Uyghur
- Uzbek
- Vietnamese
- Yao
All 114 surahs in Yoruba: the Qur’an in Yoruba.
Yoruba translation: Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni, from Quran.com. Transliteration: Quran.com. Recitation: Mishary Alafasy, from EveryAyah.com. MyDugsi is a learning aid, not a replacement for a qualified teacher.