Surah Al-Hadid in Yoruba: translation and audio
Surah 57 · الحديد · The Iron · 29 verses
Surah Al-Hadid verse by verse: the Arabic with a recitation you can repeat, the transliteration, and the Yoruba translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni. For the meaning of every word, see Surah Al-Hadid word by word in English.
Verse 1
سَبَّحَ لِلَّهِ مَا فِى ٱلسَّمَـٰوَٰتِ وَٱلْأَرْضِ ۖ وَهُوَ ٱلْعَزِيزُ ٱلْحَكِيمُ
Transliteration sabbaḥa lillahi mā fī l-samāwāti wal-arḍi wahuwa l-ʿazīzu l-ḥakīmu
Yoruba Ohunkóhun tó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ ń ṣàfọ̀mọ́ fún Allāhu. Òun sì ni Alágbára, Ọlọ́gbọ́n.
Verse 2
لَهُۥ مُلْكُ ٱلسَّمَـٰوَٰتِ وَٱلْأَرْضِ ۖ يُحْىِۦ وَيُمِيتُ ۖ وَهُوَ عَلَىٰ كُلِّ شَىْءٍ قَدِيرٌ
Transliteration lahu mul'ku l-samāwāti wal-arḍi yuḥ'yī wayumītu wahuwa ʿalā kulli shayin qadīrun
Yoruba TiRẹ̀ ni ìjọba àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Ó ń sọ ẹ̀dá di alààyè. Ó sì ń sọ ẹ̀dá di òkú. Òun ni Alágbára lórí gbogbo n̄ǹkan.
Verse 3
هُوَ ٱلْأَوَّلُ وَٱلْـَٔاخِرُ وَٱلظَّـٰهِرُ وَٱلْبَاطِنُ ۖ وَهُوَ بِكُلِّ شَىْءٍ عَلِيمٌ
Transliteration huwa l-awalu wal-ākhiru wal-ẓāhiru wal-bāṭinu wahuwa bikulli shayin ʿalīmun
Yoruba Òun ni Àkọ́kọ́ àti Ìkẹ́yìn. Ó hàn (pẹ̀lú àmì bíbẹ Rẹ̀). Ó sì pamọ́ (fún gbogbo ojú nílé ayé). Òun ni Onímọ̀ nípa gbogbo n̄ǹkan.
Verse 4
هُوَ ٱلَّذِى خَلَقَ ٱلسَّمَـٰوَٰتِ وَٱلْأَرْضَ فِى سِتَّةِ أَيَّامٍ ثُمَّ ٱسْتَوَىٰ عَلَى ٱلْعَرْشِ ۚ يَعْلَمُ مَا يَلِجُ فِى ٱلْأَرْضِ وَمَا يَخْرُجُ مِنْهَا وَمَا يَنزِلُ مِنَ ٱلسَّمَآءِ وَمَا يَعْرُجُ فِيهَا ۖ وَهُوَ مَعَكُمْ أَيْنَ مَا كُنتُمْ ۚ وَٱللَّهُ بِمَا تَعْمَلُونَ بَصِيرٌ
Transliteration huwa alladhī khalaqa l-samāwāti wal-arḍa fī sittati ayyāmin thumma is'tawā ʿalā l-ʿarshi yaʿlamu mā yaliju fī l-arḍi wamā yakhruju min'hā wamā yanzilu mina l-samāi wamā yaʿruju fīhā wahuwa maʿakum ayna mā kuntum wal-lahu bimā taʿmalūna baṣīrun
Yoruba Òun ni Ẹni tí Ó ṣẹ̀dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ fún ọjọ́ mẹ́fà. Lẹ́yìn náà, Ó gúnwà sí orí Ìtẹ́-ọlá. Ó mọ n̄ǹkan tó ń wọ inú ilẹ̀ àti n̄ǹkan tó ń jáde láti inú rẹ̀, àti n̄ǹkan tó ń sọ̀kalẹ̀ láti inú sánmọ̀ àti n̄ǹkan tó ń gùnkè sínú rẹ̀. Àti pé Ó wà pẹ̀lú yín ní ibikíbi tí ẹ bá wà (pẹ̀lú ìmọ̀ Rẹ̀).Allāhu sì ni Olùríran nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.
Verse 5
لَّهُۥ مُلْكُ ٱلسَّمَـٰوَٰتِ وَٱلْأَرْضِ ۚ وَإِلَى ٱللَّهِ تُرْجَعُ ٱلْأُمُورُ
Transliteration lahu mul'ku l-samāwāti wal-arḍi wa-ilā l-lahi tur'jaʿu l-umūru
Yoruba TiRẹ̀ ni ìjọba àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Ọ̀dọ̀ Allāhu sì ni wọ́n máa ṣẹ́rí àwọn ọ̀rọ̀ ẹ̀dá padà sí.
Verse 6
يُولِجُ ٱلَّيْلَ فِى ٱلنَّهَارِ وَيُولِجُ ٱلنَّهَارَ فِى ٱلَّيْلِ ۚ وَهُوَ عَلِيمٌۢ بِذَاتِ ٱلصُّدُورِ
Transliteration yūliju al-layla fī l-nahāri wayūliju l-nahāra fī al-layli wahuwa ʿalīmun bidhāti l-ṣudūri
Yoruba Ó ń ti òru bọ inú ọ̀sán. Ó sì ń ti ọ̀sán bọ inú òru. Òun sì ni Onímọ̀ nípa ohun tó wà nínú igbá-àyà ẹ̀dá.
Verse 7
ءَامِنُوا۟ بِٱللَّهِ وَرَسُولِهِۦ وَأَنفِقُوا۟ مِمَّا جَعَلَكُم مُّسْتَخْلَفِينَ فِيهِ ۖ فَٱلَّذِينَ ءَامَنُوا۟ مِنكُمْ وَأَنفَقُوا۟ لَهُمْ أَجْرٌ كَبِيرٌ
Transliteration āminū bil-lahi warasūlihi wa-anfiqū mimmā jaʿalakum mus'takhlafīna fīhi fa-alladhīna āmanū minkum wa-anfaqū lahum ajrun kabīrun
Yoruba Ẹ gbàgbọ́ nínú Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀. Kí ẹ sì ná nínú ohun tí Ó fi yín ṣe àrólé lórí rẹ̀. Nítorí náà, àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo nínú yín, tí wọ́n sì náwó (sí ojú ọ̀nà ẹ̀sìn), ẹ̀san tó tóbi wà fún wọn.
Verse 8
وَمَا لَكُمْ لَا تُؤْمِنُونَ بِٱللَّهِ ۙ وَٱلرَّسُولُ يَدْعُوكُمْ لِتُؤْمِنُوا۟ بِرَبِّكُمْ وَقَدْ أَخَذَ مِيثَـٰقَكُمْ إِن كُنتُم مُّؤْمِنِينَ
Transliteration wamā lakum lā tu'minūna bil-lahi wal-rasūlu yadʿūkum litu'minū birabbikum waqad akhadha mīthāqakum in kuntum mu'minīna
Yoruba Kí ni ó mu yín tí ẹ̀yin kò fi níí gbàgbọ́ ní òdodo nínú Allāhu? Òjíṣẹ́ náà sì ń pè yín nítorí kí ẹ lè gbàgbọ́ ní òdodo nínú Olúwa yín. Allāhu sì ti gba àdéhùn lọ́wọ́ yín, tí ẹ̀yin bá jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo.
Verse 9
هُوَ ٱلَّذِى يُنَزِّلُ عَلَىٰ عَبْدِهِۦٓ ءَايَـٰتٍۭ بَيِّنَـٰتٍ لِّيُخْرِجَكُم مِّنَ ٱلظُّلُمَـٰتِ إِلَى ٱلنُّورِ ۚ وَإِنَّ ٱللَّهَ بِكُمْ لَرَءُوفٌ رَّحِيمٌ
Transliteration huwa alladhī yunazzilu ʿalā ʿabdihi āyātin bayyinātin liyukh'rijakum mina l-ẓulumāti ilā l-nūri wa-inna l-laha bikum laraūfun raḥīmun
Yoruba Òun ni Ẹni tó ń sọ àwọn āyah tó yanjú kalẹ̀ fún ẹrúsìn Rẹ̀ nítorí kí ó lè mu yín kúrò nínú àwọn òkùnkùn wá sínú ìmọ́lẹ̀. Dájúdájú Allāhu ni Aláàánú, Àṣàkẹ́-ọ̀run fún yín.
Verse 10
وَمَا لَكُمْ أَلَّا تُنفِقُوا۟ فِى سَبِيلِ ٱللَّهِ وَلِلَّهِ مِيرَٰثُ ٱلسَّمَـٰوَٰتِ وَٱلْأَرْضِ ۚ لَا يَسْتَوِى مِنكُم مَّنْ أَنفَقَ مِن قَبْلِ ٱلْفَتْحِ وَقَـٰتَلَ ۚ أُو۟لَـٰٓئِكَ أَعْظَمُ دَرَجَةً مِّنَ ٱلَّذِينَ أَنفَقُوا۟ مِنۢ بَعْدُ وَقَـٰتَلُوا۟ ۚ وَكُلًّا وَعَدَ ٱللَّهُ ٱلْحُسْنَىٰ ۚ وَٱللَّهُ بِمَا تَعْمَلُونَ خَبِيرٌ
Transliteration wamā lakum allā tunfiqū fī sabīli l-lahi walillahi mīrāthu l-samāwāti wal-arḍi lā yastawī minkum man anfaqa min qabli l-fatḥi waqātala ulāika aʿẓamu darajatan mina alladhīna anfaqū min baʿdu waqātalū wakullan waʿada l-lahu l-ḥus'nā wal-lahu bimā taʿmalūna khabīrun
Yoruba Kí ni ó mu yín tí ẹ̀yin kò fi níí náwó fún ẹ̀sìn Allāhu? Ti Allāhu sì ni ogún àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Ẹni tí ó náwó ṣíwájú ṣíṣí ìlú Mọkkah, tí ó tún jagun ẹ̀sìn, kò dọ́gba láààrin yín (sí àwọn mìíràn). Àwọn wọ̀nyẹn ni ẹ̀san wọn tóbi ju ti àwọn tó náwó lẹ́yìn ìgbà náà, tí wọ́n tún jagun ẹ̀sìn. Ẹnì kọ̀ọ̀kan sì ni Allāhu ṣ’àdéhùn ẹ̀san rere fún. Allāhu sì ni Alámọ̀tán nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.
Verse 11
مَّن ذَا ٱلَّذِى يُقْرِضُ ٱللَّهَ قَرْضًا حَسَنًا فَيُضَـٰعِفَهُۥ لَهُۥ وَلَهُۥٓ أَجْرٌ كَرِيمٌ
Transliteration man dhā alladhī yuq'riḍu l-laha qarḍan ḥasanan fayuḍāʿifahu lahu walahu ajrun karīmun
Yoruba Ta ni ẹni tí ó máa yá Allāhu ní dúkìá tó dára, Ó sì máa ṣàdìpèlé rẹ̀ fún un. Ẹ̀san alápọ̀n-ọ́nlé sì tún wà fún un.
Verse 12
يَوْمَ تَرَى ٱلْمُؤْمِنِينَ وَٱلْمُؤْمِنَـٰتِ يَسْعَىٰ نُورُهُم بَيْنَ أَيْدِيهِمْ وَبِأَيْمَـٰنِهِم بُشْرَىٰكُمُ ٱلْيَوْمَ جَنَّـٰتٌ تَجْرِى مِن تَحْتِهَا ٱلْأَنْهَـٰرُ خَـٰلِدِينَ فِيهَا ۚ ذَٰلِكَ هُوَ ٱلْفَوْزُ ٱلْعَظِيمُ
Transliteration yawma tarā l-mu'minīna wal-mu'mināti yasʿā nūruhum bayna aydīhim wabi-aymānihim bush'rākumu l-yawma jannātun tajrī min taḥtihā l-anhāru khālidīna fīhā dhālika huwa l-fawzu l-ʿaẓīmu
Yoruba Ní ọjọ́ tí o máa rí àwọn onígbàgbọ́ òdodo lọ́kùnrin àti onígbàgbọ́ òdodo lóbìnrin, tí ìmọ́lẹ̀ wọn yóò máa tàn níwájú wọn àti ní ọwọ́ ọ̀tún wọn, (A óò sọ pé:) “́Ìró ìdùnnú yín ní òní ni àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra kan tí àwọn odò ń ṣàn ní ìsàlẹ̀ rẹ̀.” Olùṣegbére ni yín nínú rẹ̀. Ìyẹn sì ni èrèǹjẹ ńlá.
Verse 13
يَوْمَ يَقُولُ ٱلْمُنَـٰفِقُونَ وَٱلْمُنَـٰفِقَـٰتُ لِلَّذِينَ ءَامَنُوا۟ ٱنظُرُونَا نَقْتَبِسْ مِن نُّورِكُمْ قِيلَ ٱرْجِعُوا۟ وَرَآءَكُمْ فَٱلْتَمِسُوا۟ نُورًا فَضُرِبَ بَيْنَهُم بِسُورٍ لَّهُۥ بَابٌۢ بَاطِنُهُۥ فِيهِ ٱلرَّحْمَةُ وَظَـٰهِرُهُۥ مِن قِبَلِهِ ٱلْعَذَابُ
Transliteration yawma yaqūlu l-munāfiqūna wal-munāfiqātu lilladhīna āmanū unẓurūnā naqtabis min nūrikum qīla ir'jiʿū warāakum fal-tamisū nūran faḍuriba baynahum bisūrin lahu bābun bāṭinuhu fīhi l-raḥmatu waẓāhiruhu min qibalihi l-ʿadhābu
Yoruba Ní ọjọ́ tí àwọn ṣọ̀bẹ-ṣèlu mùsùlùmí lọ́kùnrin àti àwọn ṣọ̀bẹ-ṣèlu mùsùlùmí lóbìnrin yóò wí fún àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo pé: “Ẹ dúró fún wa ná, ẹ jẹ́ kí á mú nínú ìmọ́lẹ̀ yín.” A óò sọ fún wọn pé: “Ẹ padà s’ẹ́yìn yín, kí ẹ lọ mú ìmọ́lẹ̀.”Wọ́n sì máa fi ògiri kan tó ní ìlẹ̀kùn sáàrin wọn. Ìkẹ́ wà nínú rẹ̀ (ìyẹn ní ẹ̀yìn ìlẹ̀kùn náà ní ibi tí àwọn onígbàgbọ́ òdodo wà), ìyà sì wà ní òde rẹ̀ ní ọwọ́ iwájú rẹ̀ (ní ibi tí àwọn ṣọ̀bẹ-ṣèlu mùsùlùmí).
Verse 14
يُنَادُونَهُمْ أَلَمْ نَكُن مَّعَكُمْ ۖ قَالُوا۟ بَلَىٰ وَلَـٰكِنَّكُمْ فَتَنتُمْ أَنفُسَكُمْ وَتَرَبَّصْتُمْ وَٱرْتَبْتُمْ وَغَرَّتْكُمُ ٱلْأَمَانِىُّ حَتَّىٰ جَآءَ أَمْرُ ٱللَّهِ وَغَرَّكُم بِٱللَّهِ ٱلْغَرُورُ
Transliteration yunādūnahum alam nakun maʿakum qālū balā walākinnakum fatantum anfusakum watarabbaṣtum wa-ir'tabtum wagharratkumu l-amāniyu ḥattā jāa amru l-lahi wagharrakum bil-lahi l-gharūru
Yoruba (Àwọn ṣọ̀bẹ-ṣèlu mùsùlùmí) yóò pe (àwọn onígbàgbọ́ òdodo) pé: “́Ṣé àwa kò ti wà pẹ̀lú yín ni?”́ Wọ́n sọ pé: “́Rárá, ṣùgbọ́n ẹ kó ìyọnu bá ẹ̀mí ara yín (nípasẹ̀ ìṣọ̀bẹ-ṣèlu), ẹ retí ìparun (wá), ẹ sì ṣeyèméjì (sí òdodo). Àwọn ìfẹ́-ọkàn àti ọ̀rọ̀ irọ́ sì tàn yín jẹ títí àṣẹ Allāhu fi dé. Àti pé (Èṣù) ẹlẹ́tàn sì tàn yín jẹ nípa Allāhu.
Verse 15
فَٱلْيَوْمَ لَا يُؤْخَذُ مِنكُمْ فِدْيَةٌ وَلَا مِنَ ٱلَّذِينَ كَفَرُوا۟ ۚ مَأْوَىٰكُمُ ٱلنَّارُ ۖ هِىَ مَوْلَىٰكُمْ ۖ وَبِئْسَ ٱلْمَصِيرُ
Transliteration fal-yawma lā yu'khadhu minkum fid'yatun walā mina alladhīna kafarū mawākumu l-nāru hiya mawlākum wabi'sa l-maṣīru
Yoruba Nítorí náà, ní òní Àwa kò níí gba ìtánràn kan ní ọwọ́ ẹ̀yin àti àwọn tó ṣàì gbàgbọ́. Iná ni ibùgbé yín. Òhun l’ó tọ́ si yín. Ìkángun náà sì burú.
Verse 16
۞ أَلَمْ يَأْنِ لِلَّذِينَ ءَامَنُوٓا۟ أَن تَخْشَعَ قُلُوبُهُمْ لِذِكْرِ ٱللَّهِ وَمَا نَزَلَ مِنَ ٱلْحَقِّ وَلَا يَكُونُوا۟ كَٱلَّذِينَ أُوتُوا۟ ٱلْكِتَـٰبَ مِن قَبْلُ فَطَالَ عَلَيْهِمُ ٱلْأَمَدُ فَقَسَتْ قُلُوبُهُمْ ۖ وَكَثِيرٌ مِّنْهُمْ فَـٰسِقُونَ
Transliteration alam yani lilladhīna āmanū an takhshaʿa qulūbuhum lidhik'ri l-lahi wamā nazala mina l-ḥaqi walā yakūnū ka-alladhīna ūtū l-kitāba min qablu faṭāla ʿalayhimu l-amadu faqasat qulūbuhum wakathīrun min'hum fāsiqūna
Yoruba Ṣé àkókò kò tí ì tó fún àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo pé kí ọkàn wọn rọ̀ fún ìrántí Allāhu àti ohun tó sọ̀kalẹ̀ nínú òdodo (ìyẹn, al-Ƙur’ān). Kí wọ́n sì má ṣe dà bí àwọn tí A fún ní Tírà ní ìṣáájú; ìgbà pẹ́ lórí wọn, ọkàn wọn bá le. Ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ nínú wọn sì ni òbìlẹ̀jẹ́.
Verse 17
ٱعْلَمُوٓا۟ أَنَّ ٱللَّهَ يُحْىِ ٱلْأَرْضَ بَعْدَ مَوْتِهَا ۚ قَدْ بَيَّنَّا لَكُمُ ٱلْـَٔايَـٰتِ لَعَلَّكُمْ تَعْقِلُونَ
Transliteration iʿ'lamū anna l-laha yuḥ'yī l-arḍa baʿda mawtihā qad bayyannā lakumu l-āyāti laʿallakum taʿqilūna
Yoruba Ẹ mọ̀ pé dájúdájú Allāhu l’Ó ń sọ ilẹ̀ di àyè lẹ́yìn tí ilẹ̀ ti kú. A kúkú ti ṣàlàyé àwọn āyah náá nítorí kí ẹ lè ṣe làákàyè.
Verse 18
إِنَّ ٱلْمُصَّدِّقِينَ وَٱلْمُصَّدِّقَـٰتِ وَأَقْرَضُوا۟ ٱللَّهَ قَرْضًا حَسَنًا يُضَـٰعَفُ لَهُمْ وَلَهُمْ أَجْرٌ كَرِيمٌ
Transliteration inna l-muṣadiqīna wal-muṣadiqāti wa-aqraḍū l-laha qarḍan ḥasanan yuḍāʿafu lahum walahum ajrun karīmun
Yoruba Dájúdájú àwọn olùtọrẹ lọ́kùnrin àti àwọn olùtọrẹ lóbìnrin, tí wọ́n tún yá Allāhu ní dúkìá tó dára, (Allāhu) yóò ṣàdìpèlé rẹ̀ fún wọn. Ẹ̀san alápọ̀n-ọ́nlé sì wà fún wọn.
Verse 19
وَٱلَّذِينَ ءَامَنُوا۟ بِٱللَّهِ وَرُسُلِهِۦٓ أُو۟لَـٰٓئِكَ هُمُ ٱلصِّدِّيقُونَ ۖ وَٱلشُّهَدَآءُ عِندَ رَبِّهِمْ لَهُمْ أَجْرُهُمْ وَنُورُهُمْ ۖ وَٱلَّذِينَ كَفَرُوا۟ وَكَذَّبُوا۟ بِـَٔايَـٰتِنَآ أُو۟لَـٰٓئِكَ أَصْحَـٰبُ ٱلْجَحِيمِ
Transliteration wa-alladhīna āmanū bil-lahi warusulihi ulāika humu l-ṣidīqūna wal-shuhadāu ʿinda rabbihim lahum ajruhum wanūruhum wa-alladhīna kafarū wakadhabū biāyātinā ulāika aṣḥābu l-jaḥīmi
Yoruba Àwọn tó gbàgbọ́ nínú Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀, àwọn wọ̀nyẹn ni àwọn olódodo àti ẹlẹ́rìí ní ọ̀dọ̀ Olúwa wọn. Ẹ̀san wọn àti ìmọ́lẹ̀ wọn wà fún wọn. Àwọn tó sì ṣàì gbàgbọ́, tí wọ́n tún pe àwọn āyah Wa ní irọ́, àwọn wọ̀nyẹn ni èrò inú iná Jẹhīm.
Verse 20
ٱعْلَمُوٓا۟ أَنَّمَا ٱلْحَيَوٰةُ ٱلدُّنْيَا لَعِبٌ وَلَهْوٌ وَزِينَةٌ وَتَفَاخُرٌۢ بَيْنَكُمْ وَتَكَاثُرٌ فِى ٱلْأَمْوَٰلِ وَٱلْأَوْلَـٰدِ ۖ كَمَثَلِ غَيْثٍ أَعْجَبَ ٱلْكُفَّارَ نَبَاتُهُۥ ثُمَّ يَهِيجُ فَتَرَىٰهُ مُصْفَرًّا ثُمَّ يَكُونُ حُطَـٰمًا ۖ وَفِى ٱلْـَٔاخِرَةِ عَذَابٌ شَدِيدٌ وَمَغْفِرَةٌ مِّنَ ٱللَّهِ وَرِضْوَٰنٌ ۚ وَمَا ٱلْحَيَوٰةُ ٱلدُّنْيَآ إِلَّا مَتَـٰعُ ٱلْغُرُورِ
Transliteration iʿ'lamū annamā l-ḥayatu l-dun'yā laʿibun walahwun wazīnatun watafākhurun baynakum watakāthurun fī l-amwāli wal-awlādi kamathali ghaythin aʿjaba l-kufāra nabātuhu thumma yahīju fatarāhu muṣ'farran thumma yakūnu ḥuṭāman wafī l-ākhirati ʿadhābun shadīdun wamaghfiratun mina l-lahi wariḍ'wānun wamā l-ḥayatu l-dun'yā illā matāʿu l-ghurūri
Yoruba Ẹ mọ̀ pé dájúdájú ìṣẹ̀mí ayé yìí jẹ́ eré, ìranù, ọ̀ṣọ́, ṣíṣe ìyanràn láààrin ara yín àti wíwá ọ̀pọ̀ dúkìá àti ọmọ. (Ìwọ̀nyí) dà bí òjò (tó mú irúgbìn jáde). Irúgbìn rẹ̀ sì ń jọ àwọn aláìgbàgbọ́ lójú. Lẹ́yìn náà, ó máa gbẹ. O sì máa rí i ní pípọ́n. Lẹ́yìn náà, ó máa di rírún (tí atẹ́gùn máa fẹ́ dànù). Ìyà líle àti àforíjìn pẹ̀lú ìyọ́nú láti ọ̀dọ̀ Allāhu sì wà ní ọ̀run. Kí sì ni ìṣẹ̀mí ayé yìí bí kò ṣe ìgbádùn ẹ̀tàn.
Verse 21
سَابِقُوٓا۟ إِلَىٰ مَغْفِرَةٍ مِّن رَّبِّكُمْ وَجَنَّةٍ عَرْضُهَا كَعَرْضِ ٱلسَّمَآءِ وَٱلْأَرْضِ أُعِدَّتْ لِلَّذِينَ ءَامَنُوا۟ بِٱللَّهِ وَرُسُلِهِۦ ۚ ذَٰلِكَ فَضْلُ ٱللَّهِ يُؤْتِيهِ مَن يَشَآءُ ۚ وَٱللَّهُ ذُو ٱلْفَضْلِ ٱلْعَظِيمِ
Transliteration sābiqū ilā maghfiratin min rabbikum wajannatin ʿarḍuhā kaʿarḍi l-samāi wal-arḍi uʿiddat lilladhīna āmanū bil-lahi warusulihi dhālika faḍlu l-lahi yu'tīhi man yashāu wal-lahu dhū l-faḍli l-ʿaẓīmi
Yoruba Ẹ yára lọ síbi àforíjìn láti ọ̀dọ̀ Olúwa yín àti Ọgbà Ìdẹ̀ra tí fífẹ̀ rẹ̀ dà bí fífẹ̀ sánmọ̀ àti ilẹ̀. Wọ́n pa á lésè sílẹ̀ de àwọn tó gbàgbọ́ nínú Allāhu àti àwọn Òjíṣẹ́ Rẹ̀. Ìyẹn ni oore àjùlọ Allāhu tí Ó ń fún ẹni tí Ó bá fẹ́. Allāhu sì ni Olóore ńlá.
Verse 22
مَآ أَصَابَ مِن مُّصِيبَةٍ فِى ٱلْأَرْضِ وَلَا فِىٓ أَنفُسِكُمْ إِلَّا فِى كِتَـٰبٍ مِّن قَبْلِ أَن نَّبْرَأَهَآ ۚ إِنَّ ذَٰلِكَ عَلَى ٱللَّهِ يَسِيرٌ
Transliteration mā aṣāba min muṣībatin fī l-arḍi walā fī anfusikum illā fī kitābin min qabli an nabra-ahā inna dhālika ʿalā l-lahi yasīrun
Yoruba Àdánwò kan kò níí ṣẹlẹ̀ ní orí ilẹ̀ tàbí (kí ó ṣẹlẹ̀) sí ẹ̀yin àyàfi kí ó ti wà nínú Tírà ṣíwájú kí A tó dá ẹ̀dá. Dájúdájú ìyẹn rọ̀rùn fún Allāhu.
Verse 23
لِّكَيْلَا تَأْسَوْا۟ عَلَىٰ مَا فَاتَكُمْ وَلَا تَفْرَحُوا۟ بِمَآ ءَاتَىٰكُمْ ۗ وَٱللَّهُ لَا يُحِبُّ كُلَّ مُخْتَالٍ فَخُورٍ
Transliteration likaylā tasaw ʿalā mā fātakum walā tafraḥū bimā ātākum wal-lahu lā yuḥibbu kulla mukh'tālin fakhūrin
Yoruba (Ìṣẹ̀lẹ̀ ń tọ kádàrá lẹ́yìn) nítorí kí ẹ má ṣe banújẹ́ lórí ohun tí ó bá bọ́ fún yín àti nítorí kí ẹ má ṣe yọ àyọ̀jù lórí ohun tí Ó bá fún yín. Allāhu kò sì nífẹ̀ẹ́ sí gbogbo onígbèéraga, onífáàrí.
Verse 24
ٱلَّذِينَ يَبْخَلُونَ وَيَأْمُرُونَ ٱلنَّاسَ بِٱلْبُخْلِ ۗ وَمَن يَتَوَلَّ فَإِنَّ ٱللَّهَ هُوَ ٱلْغَنِىُّ ٱلْحَمِيدُ
Transliteration alladhīna yabkhalūna wayamurūna l-nāsa bil-bukh'li waman yatawalla fa-inna l-laha huwa l-ghaniyu l-ḥamīdu
Yoruba Àwọn tó ń ṣahun, tí wọ́n sì ń pa àwọn ènìyàn láṣẹ ahun ṣíṣe (kí wọ́n mọ̀ pé) ẹnikẹ́ni tí ó bá pẹ̀yìndà (tí kò náwó fún ẹ̀sìn), dájúdájú Allāhu, Òun ni Ọlọ́rọ̀, Ẹlẹ́yìn.
Verse 25
لَقَدْ أَرْسَلْنَا رُسُلَنَا بِٱلْبَيِّنَـٰتِ وَأَنزَلْنَا مَعَهُمُ ٱلْكِتَـٰبَ وَٱلْمِيزَانَ لِيَقُومَ ٱلنَّاسُ بِٱلْقِسْطِ ۖ وَأَنزَلْنَا ٱلْحَدِيدَ فِيهِ بَأْسٌ شَدِيدٌ وَمَنَـٰفِعُ لِلنَّاسِ وَلِيَعْلَمَ ٱللَّهُ مَن يَنصُرُهُۥ وَرُسُلَهُۥ بِٱلْغَيْبِ ۚ إِنَّ ٱللَّهَ قَوِىٌّ عَزِيزٌ
Transliteration laqad arsalnā rusulanā bil-bayināti wa-anzalnā maʿahumu l-kitāba wal-mīzāna liyaqūma l-nāsu bil-qis'ṭi wa-anzalnā l-ḥadīda fīhi basun shadīdun wamanāfiʿu lilnnāsi waliyaʿlama l-lahu man yanṣuruhu warusulahu bil-ghaybi inna l-laha qawiyyun ʿazīzun
Yoruba Dájúdájú A fi àwọn ẹ̀rí tó yanjú rán àwọn Òjíṣẹ́ Wa. A sọ Tírà àti òṣùwọ̀n kalẹ̀ fún wọn nítorí kí àwọn ènìyàn lè rí déédé ṣe (láààrin ara wọn). A tún sọ irin kalẹ̀. Ohun ìjagun tó lágbára àti àwọn àǹfààní wà nínú rẹ̀ fún àwọn ènìyàn nítorí kí Allāhu lè ṣàfi hàn ẹni tó ń ran (ẹ̀sìn) Rẹ̀ àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀ lọ́wọ́ ní ìkọ̀kọ̀. Dájúdájú Allāhu ni Alágbára, Olùborí.
Verse 26
وَلَقَدْ أَرْسَلْنَا نُوحًا وَإِبْرَٰهِيمَ وَجَعَلْنَا فِى ذُرِّيَّتِهِمَا ٱلنُّبُوَّةَ وَٱلْكِتَـٰبَ ۖ فَمِنْهُم مُّهْتَدٍ ۖ وَكَثِيرٌ مِّنْهُمْ فَـٰسِقُونَ
Transliteration walaqad arsalnā nūḥan wa-ib'rāhīma wajaʿalnā fī dhurriyyatihimā l-nubuwata wal-kitāba famin'hum muh'tadin wakathīrun min'hum fāsiqūna
Yoruba Dájúdájú A fi iṣẹ́ rán (Ànábì) Nūh àti (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm. A fi ipò Ànábì sínú àwọn àrọ́mọdọ́mọ àwọn méjèèjì pẹ̀lú Tírà (tí A fún wọn). Olùmọ̀nà wà nínú wọn. Ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ nínú wọn sì ni òbìlẹ̀jẹ́.
Verse 27
ثُمَّ قَفَّيْنَا عَلَىٰٓ ءَاثَـٰرِهِم بِرُسُلِنَا وَقَفَّيْنَا بِعِيسَى ٱبْنِ مَرْيَمَ وَءَاتَيْنَـٰهُ ٱلْإِنجِيلَ وَجَعَلْنَا فِى قُلُوبِ ٱلَّذِينَ ٱتَّبَعُوهُ رَأْفَةً وَرَحْمَةً وَرَهْبَانِيَّةً ٱبْتَدَعُوهَا مَا كَتَبْنَـٰهَا عَلَيْهِمْ إِلَّا ٱبْتِغَآءَ رِضْوَٰنِ ٱللَّهِ فَمَا رَعَوْهَا حَقَّ رِعَايَتِهَا ۖ فَـَٔاتَيْنَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُوا۟ مِنْهُمْ أَجْرَهُمْ ۖ وَكَثِيرٌ مِّنْهُمْ فَـٰسِقُونَ
Transliteration thumma qaffaynā ʿalā āthārihim birusulinā waqaffaynā biʿīsā ib'ni maryama waātaynāhu l-injīla wajaʿalnā fī qulūbi alladhīna ittabaʿūhu rafatan waraḥmatan warahbāniyyatan ib'tadaʿūhā mā katabnāhā ʿalayhim illā ib'tighāa riḍ'wāni l-lahi famā raʿawhā ḥaqqa riʿāyatihā faātaynā alladhīna āmanū min'hum ajrahum wakathīrun min'hum fāsiqūna
Yoruba Lẹ́yìn náà, A fi àwọn Òjíṣẹ́ Wa tẹ̀lé orípa wọn. A sì mú ‘Īsā ọmọ Mọryam tẹ̀lé wọn. A fún un ni al-’Injīl. A fi àánú àti ìkẹ́ sínú ọkàn àwọn tó tẹ̀lé e. Àṣà àdáwà (láì lọ́kọ tàbí láì laya) wọ́n ṣe àdádáálẹ̀ rẹ̀ ni. A kò ṣe é ní ọ̀ran-anyàn fún wọn. (Wọn kò sì ṣe àdáwà fún kiní kan) bí kò ṣe láti fi wá ìyọ́nú Allāhu. Wọn kò sì rí i ṣọ́ bí ó ṣe yẹ kí wọ́n ṣọ́ ọ. Nítorí náà, A fún àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo nínú wọn ní ẹ̀san wọn. Ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ nínú wọn sì ni òbìlẹ̀jẹ́.1
Verse 28
يَـٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُوا۟ ٱتَّقُوا۟ ٱللَّهَ وَءَامِنُوا۟ بِرَسُولِهِۦ يُؤْتِكُمْ كِفْلَيْنِ مِن رَّحْمَتِهِۦ وَيَجْعَل لَّكُمْ نُورًا تَمْشُونَ بِهِۦ وَيَغْفِرْ لَكُمْ ۚ وَٱللَّهُ غَفُورٌ رَّحِيمٌ
Transliteration yāayyuhā alladhīna āmanū ittaqū l-laha waāminū birasūlihi yu'tikum kif'layni min raḥmatihi wayajʿal lakum nūran tamshūna bihi wayaghfir lakum wal-lahu ghafūrun raḥīmun
Yoruba Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ bẹ̀rù Allāhu, kí ẹ sì gba Òjíṣẹ́ Rẹ̀ gbọ́ ní òdodo, Allāhu máa fún yín ní ìlọ́po méjì nínú ìkẹ́ Rẹ̀, Ó máa fún yín ní ìmọ́lẹ̀ tí ẹ óò máa fi rìn,Ó sì máa forí jìn yín. Allāhu sì ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.
Verse 29
لِّئَلَّا يَعْلَمَ أَهْلُ ٱلْكِتَـٰبِ أَلَّا يَقْدِرُونَ عَلَىٰ شَىْءٍ مِّن فَضْلِ ٱللَّهِ ۙ وَأَنَّ ٱلْفَضْلَ بِيَدِ ٱللَّهِ يُؤْتِيهِ مَن يَشَآءُ ۚ وَٱللَّهُ ذُو ٱلْفَضْلِ ٱلْعَظِيمِ
Transliteration li-allā yaʿlama ahlu l-kitābi allā yaqdirūna ʿalā shayin min faḍli l-lahi wa-anna l-faḍla biyadi l-lahi yu'tīhi man yashāu wal-lahu dhū l-faḍli l-ʿaẓīmi
Yoruba (Allāhu ṣe bẹ́ẹ̀ fún yín) nítorí kí àwọn ahlu-l-kitāb lè mọ̀ pé àwọn kò ní agbára lórí kiní kan nínú oore àjùlọ Allāhu. Àti pé dájúdájú oore àjùlọ, ọwọ́ Allāhu l’ó wà. Ó sì ń fún ẹni tí Ó bá fẹ́. Allāhu sì ni Olóore ńlá.
Read Surah Al-Hadid in another language
- English (word by word)
- Albanian
- Amazigh
- Amharic
- Assamese
- Azerbaijani
- Bambara
- Bangla
- Bosnian
- Bulgarian
- Chechen
- Chinese
- Czech
- Dari
- Dhivehi
- Dutch
- Finnish
- French
- German
- Gujarati
- Hausa
- Hebrew
- Hindi
- Indonesian
- Italian
- Japanese
- Kannada
- Kazakh
- Khmer
- Kinyarwanda
- Korean
- Kurdish
- Luganda
- Malay
- Malayalam
- Maranao
- Marathi
- Nepali
- Norwegian
- Oromo
- Pashto
- Persian
- Polish
- Portuguese
- Romanian
- Russian
- Sindhi
- Sinhala
- Somali
- Spanish
- Swahili
- Swedish
- Tagalog
- Tajik
- Tamil
- Tatar
- Telugu
- Thai
- Turkish
- Ukrainian
- Urdu
- Uyghur
- Uzbek
- Vietnamese
- Yao
All 114 surahs in Yoruba: the Qur’an in Yoruba.
Yoruba translation: Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni, from Quran.com. Transliteration: Quran.com. Recitation: Mishary Alafasy, from EveryAyah.com. MyDugsi is a learning aid, not a replacement for a qualified teacher.