MyDugsiStart learning

Surah Al-Fath in Yoruba: translation and audio

Surah 48 · الفتح · The Victory · 29 verses

Surah Al-Fath verse by verse: the Arabic with a recitation you can repeat, the transliteration, and the Yoruba translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni. For the meaning of every word, see Surah Al-Fath word by word in English.

Verse 1

إِنَّا فَتَحْنَا لَكَ فَتْحًا مُّبِينًا

Transliteration innā fataḥnā laka fatḥan mubīnan

Yoruba Dájúdájú Àwa ṣẹ́gun fún ọ ní ìṣẹ́gun tó fojú hàn

Verse 2

لِّيَغْفِرَ لَكَ ٱللَّهُ مَا تَقَدَّمَ مِن ذَنۢبِكَ وَمَا تَأَخَّرَ وَيُتِمَّ نِعْمَتَهُۥ عَلَيْكَ وَيَهْدِيَكَ صِرَٰطًا مُّسْتَقِيمًا

Transliteration liyaghfira laka l-lahu mā taqaddama min dhanbika wamā ta-akhara wayutimma niʿ'matahu ʿalayka wayahdiyaka ṣirāṭan mus'taqīman

Yoruba nítorí kí Allāhu lè ṣàforíjìn ohun tí ó ṣíwájú nínú àṣìṣe rẹ àti ohun tí ó kẹ́yìn (nínú rẹ̀),àti nítorí kí Ó lè ṣàṣepé ìdẹ̀ra Rẹ̀ lé ọ lórí àti nítorí kí Ó lè fi ẹsẹ̀ rẹ rinlẹ̀ sójú ọ̀nà tààrà (’Islām),

Verse 3

وَيَنصُرَكَ ٱللَّهُ نَصْرًا عَزِيزًا

Transliteration wayanṣuraka l-lahu naṣran ʿazīzan

Yoruba àti nítorí kí Allāhu lè ṣàrànṣe fún ọ ní àrànṣe tó lágbára.

Verse 4

هُوَ ٱلَّذِىٓ أَنزَلَ ٱلسَّكِينَةَ فِى قُلُوبِ ٱلْمُؤْمِنِينَ لِيَزْدَادُوٓا۟ إِيمَـٰنًا مَّعَ إِيمَـٰنِهِمْ ۗ وَلِلَّهِ جُنُودُ ٱلسَّمَـٰوَٰتِ وَٱلْأَرْضِ ۚ وَكَانَ ٱللَّهُ عَلِيمًا حَكِيمًا

Transliteration huwa alladhī anzala l-sakīnata fī qulūbi l-mu'minīna liyazdādū īmānan maʿa īmānihim walillahi junūdu l-samāwāti wal-arḍi wakāna l-lahu ʿalīman ḥakīman

Yoruba Òun ni Ẹni tí Ó sọ ìfàyàbalẹ̀ sínú ọkàn àwọn onígbàgbọ́ òdodo nítorí kí wọ́n lè lékún ní ìgbàgbọ́ sí ìgbàgbọ́ wọn. Ti Allāhu sì ni àwọn ọmọ ogun sánmọ̀ àti ilẹ̀. Allāhu sì ń jẹ́ Onímọ̀, Ọlọ́gbọ́n.

Verse 5

لِّيُدْخِلَ ٱلْمُؤْمِنِينَ وَٱلْمُؤْمِنَـٰتِ جَنَّـٰتٍ تَجْرِى مِن تَحْتِهَا ٱلْأَنْهَـٰرُ خَـٰلِدِينَ فِيهَا وَيُكَفِّرَ عَنْهُمْ سَيِّـَٔاتِهِمْ ۚ وَكَانَ ذَٰلِكَ عِندَ ٱللَّهِ فَوْزًا عَظِيمًا

Transliteration liyud'khila l-mu'minīna wal-mu'mināti jannātin tajrī min taḥtihā l-anhāru khālidīna fīhā wayukaffira ʿanhum sayyiātihim wakāna dhālika ʿinda l-lahi fawzan ʿaẓīman

Yoruba (Ó ṣe bẹ́ẹ̀ fún wọn) nítorí kí Ó lè mú àwọn onígbàgbọ́ òdodo lọ́kùnrin àti onígbàgbọ́ òdodo lóbìnrin wọ inú àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra kan, èyí tí àwọn odò ń ṣàn ní ìsàlẹ̀ rẹ, olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀, àti nítorí kí Ó lè pa àwọn àṣìṣe wọn rẹ́. Ìyẹn sì jẹ́ èrèǹjẹ ńlá ní ọ̀dọ̀ Allāhu.

Verse 6

وَيُعَذِّبَ ٱلْمُنَـٰفِقِينَ وَٱلْمُنَـٰفِقَـٰتِ وَٱلْمُشْرِكِينَ وَٱلْمُشْرِكَـٰتِ ٱلظَّآنِّينَ بِٱللَّهِ ظَنَّ ٱلسَّوْءِ ۚ عَلَيْهِمْ دَآئِرَةُ ٱلسَّوْءِ ۖ وَغَضِبَ ٱللَّهُ عَلَيْهِمْ وَلَعَنَهُمْ وَأَعَدَّ لَهُمْ جَهَنَّمَ ۖ وَسَآءَتْ مَصِيرًا

Transliteration wayuʿadhiba l-munāfiqīna wal-munāfiqāti wal-mush'rikīna wal-mush'rikāti l-ẓānīna bil-lahi ẓanna l-sawi ʿalayhim dāiratu l-sawi waghaḍiba l-lahu ʿalayhim walaʿanahum wa-aʿadda lahum jahannama wasāat maṣīran

Yoruba Àti nítorí kí Ó lè fìyà jẹ àwọn ṣọ̀bẹ-ṣèlu mùsùlùmí lọ́kùnrin àti àwọn ṣọ̀bẹ-ṣèlu mùsùlùmí lóbìnrin, pẹ̀lú àwọn ọ̀ṣẹbọ lọ́kùnrin àti àwọn ọ̀ṣẹbọ lóbìnrin, àwọn eléròkérò nípa Allāhu ní ti èrò aburú. Àpadàsí aburú ń bẹ fún wọn. Allāhu ti bínú sí wọn. Ó ti ṣẹ́bi lé wọn. Ó sì ti pèsè iná Jahanamọ sílẹ̀ dè wọ́n. Ó sì burú ní ìkángun.

Verse 7

وَلِلَّهِ جُنُودُ ٱلسَّمَـٰوَٰتِ وَٱلْأَرْضِ ۚ وَكَانَ ٱللَّهُ عَزِيزًا حَكِيمًا

Transliteration walillahi junūdu l-samāwāti wal-arḍi wakāna l-lahu ʿazīzan ḥakīman

Yoruba Ti Allāhu sì ni àwọn ọmọ ogun sánmọ̀ àti ilẹ̀. Allāhu sì ń jẹ́ Alágbára, Ọlọ́gbọ́n.

Verse 8

إِنَّآ أَرْسَلْنَـٰكَ شَـٰهِدًا وَمُبَشِّرًا وَنَذِيرًا

Transliteration innā arsalnāka shāhidan wamubashiran wanadhīran

Yoruba Dájúdájú Àwa rán ọ níṣẹ́ (pé kí o jẹ́) olùjẹ́rìí, oníròó-ìdùnnú àti olùkìlọ̀

Verse 9

لِّتُؤْمِنُوا۟ بِٱللَّهِ وَرَسُولِهِۦ وَتُعَزِّرُوهُ وَتُوَقِّرُوهُ وَتُسَبِّحُوهُ بُكْرَةً وَأَصِيلًا

Transliteration litu'minū bil-lahi warasūlihi watuʿazzirūhu watuwaqqirūhu watusabbiḥūhu buk'ratan wa-aṣīlan

Yoruba nítorí kí ẹ lè ní ìgbàgbọ́ òdodo nínú Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀, àti (nítorí kí) ẹ lè ṣe ìrànlọ́wọ́ fún (Òjíṣẹ́ náà) àti nítorí kí ẹ lè pàtàkì rẹ̀, àti nítorí kí ẹ lè ṣàfọ̀mọ́ fún (Allāhu) ní òwúrọ̀ àti ní ìrọ̀lẹ́.

Verse 10

إِنَّ ٱلَّذِينَ يُبَايِعُونَكَ إِنَّمَا يُبَايِعُونَ ٱللَّهَ يَدُ ٱللَّهِ فَوْقَ أَيْدِيهِمْ ۚ فَمَن نَّكَثَ فَإِنَّمَا يَنكُثُ عَلَىٰ نَفْسِهِۦ ۖ وَمَنْ أَوْفَىٰ بِمَا عَـٰهَدَ عَلَيْهُ ٱللَّهَ فَسَيُؤْتِيهِ أَجْرًا عَظِيمًا

Transliteration inna alladhīna yubāyiʿūnaka innamā yubāyiʿūna l-laha yadu l-lahi fawqa aydīhim faman nakatha fa-innamā yankuthu ʿalā nafsihi waman awfā bimā ʿāhada ʿalayhu l-laha fasayu'tīhi ajran ʿaẓīman

Yoruba Dájúdájú àwọn tó ń ṣàdéhùn fún ọ (pé àwọn máa dúró tì ọ́ lójú ogun), dájúdájú Allāhu ni wọ́n ń ṣàdéhùn fún. Ọwọ́ Allāhu wà lókè ọwọ́ wọn.Ẹnikẹ́ni tí ó bá tú àdéhùn rẹ̀, ó tú u fún ẹ̀mí ara rẹ̀. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì mú àdéhùn tó ṣe fún Allāhu ṣẹ, (Allāhu) yóò fún un ní ẹ̀san ńlá.

Verse 11

سَيَقُولُ لَكَ ٱلْمُخَلَّفُونَ مِنَ ٱلْأَعْرَابِ شَغَلَتْنَآ أَمْوَٰلُنَا وَأَهْلُونَا فَٱسْتَغْفِرْ لَنَا ۚ يَقُولُونَ بِأَلْسِنَتِهِم مَّا لَيْسَ فِى قُلُوبِهِمْ ۚ قُلْ فَمَن يَمْلِكُ لَكُم مِّنَ ٱللَّهِ شَيْـًٔا إِنْ أَرَادَ بِكُمْ ضَرًّا أَوْ أَرَادَ بِكُمْ نَفْعًۢا ۚ بَلْ كَانَ ٱللَّهُ بِمَا تَعْمَلُونَ خَبِيرًۢا

Transliteration sayaqūlu laka l-mukhalafūna mina l-aʿrābi shaghalatnā amwālunā wa-ahlūnā fa-is'taghfir lanā yaqūlūna bi-alsinatihim mā laysa fī qulūbihim qul faman yamliku lakum mina l-lahi shayan in arāda bikum ḍarran aw arāda bikum nafʿan bal kāna l-lahu bimā taʿmalūna khabīran

Yoruba Àwọn olùsásẹ́yìn fún ogun ẹ̀sìn nínú àwọn Lárúbáwá oko yóò máa wí fún ọ pé: “Àwọn dúkìá wa àti àwọn ará ilé wa l’ó kó àìrójú bá wa. Nítorí náà, tọrọ àforíjìn fún wa.” Wọ́n ń fi ahọ́n wọn wí ohun tí kò sí nínú ọkàn wọn. Sọ pé: “Ta ni ó ní ìkápá kiní kan fún yín lọ́dọ̀ Allāhu tí Ó bá gbèrò (láti fi) ìnira kàn yín tàbí tí Ó bá gbèrò àǹfààní kan fún yín? Rárá (kò sí). Allāhu sì ń jẹ́ Alámọ̀tán nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.”

Verse 12

بَلْ ظَنَنتُمْ أَن لَّن يَنقَلِبَ ٱلرَّسُولُ وَٱلْمُؤْمِنُونَ إِلَىٰٓ أَهْلِيهِمْ أَبَدًا وَزُيِّنَ ذَٰلِكَ فِى قُلُوبِكُمْ وَظَنَنتُمْ ظَنَّ ٱلسَّوْءِ وَكُنتُمْ قَوْمًۢا بُورًا

Transliteration bal ẓanantum an lan yanqaliba l-rasūlu wal-mu'minūna ilā ahlīhim abadan wazuyyina dhālika fī qulūbikum waẓanantum ẓanna l-sawi wakuntum qawman būran

Yoruba Rárá (kì í ṣe iṣẹ́ kan l’ó di yín lọ́wọ́ láti lọ jagun, àmọ́) ẹ ti lérò pé Òjíṣẹ́ àti àwọn onígbàgbọ́ òdodo kò níí padà sí ọ̀dọ̀ ará ilé wọn mọ́ láéláé. Wọ́n ṣe ìyẹn ni ọ̀ṣọ́ sínú ọkàn yín. Ẹ sì ro èrò aburú. Ẹ sì jẹ́ ìjọ ìparun.

Verse 13

وَمَن لَّمْ يُؤْمِنۢ بِٱللَّهِ وَرَسُولِهِۦ فَإِنَّآ أَعْتَدْنَا لِلْكَـٰفِرِينَ سَعِيرًا

Transliteration waman lam yu'min bil-lahi warasūlihi fa-innā aʿtadnā lil'kāfirīna saʿīran

Yoruba Ẹnikẹ́ni tí kò bá gbàgbọ́ nínú Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀, dájúdájú Àwa ti pèsè Iná sílẹ̀ de àwọn aláìgbàgbọ́.

Verse 14

وَلِلَّهِ مُلْكُ ٱلسَّمَـٰوَٰتِ وَٱلْأَرْضِ ۚ يَغْفِرُ لِمَن يَشَآءُ وَيُعَذِّبُ مَن يَشَآءُ ۚ وَكَانَ ٱللَّهُ غَفُورًا رَّحِيمًا

Transliteration walillahi mul'ku l-samāwāti wal-arḍi yaghfiru liman yashāu wayuʿadhibu man yashāu wakāna l-lahu ghafūran raḥīman

Yoruba Ti Allāhu ni ìjọba àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Ó ń ṣàforíjìn fún ẹni tí Ó bá fẹ́. Ó sì ń jẹ ẹni tí Ó bá fẹ́ níyà.Allāhu sì ń jẹ́ Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.

Verse 15

سَيَقُولُ ٱلْمُخَلَّفُونَ إِذَا ٱنطَلَقْتُمْ إِلَىٰ مَغَانِمَ لِتَأْخُذُوهَا ذَرُونَا نَتَّبِعْكُمْ ۖ يُرِيدُونَ أَن يُبَدِّلُوا۟ كَلَـٰمَ ٱللَّهِ ۚ قُل لَّن تَتَّبِعُونَا كَذَٰلِكُمْ قَالَ ٱللَّهُ مِن قَبْلُ ۖ فَسَيَقُولُونَ بَلْ تَحْسُدُونَنَا ۚ بَلْ كَانُوا۟ لَا يَفْقَهُونَ إِلَّا قَلِيلًا

Transliteration sayaqūlu l-mukhalafūna idhā inṭalaqtum ilā maghānima litakhudhūhā dharūnā nattabiʿ'kum yurīdūna an yubaddilū kalāma l-lahi qul lan tattabiʿūnā kadhālikum qāla l-lahu min qablu fasayaqūlūna bal taḥsudūnanā bal kānū lā yafqahūna illā qalīlan

Yoruba Àwọn olùsásẹ́yìn fún ogun (Hudaebiyyah) ń wí pé: “Nígbà tí ẹ bá ń lọ síbi ọrọ̀-ogun (Kọebar) nítorí kí ẹ lè rí i kó, ẹ fi wá sílẹ̀ kí á lè tẹ̀lé yín lọ.” (Àwọn olùsásẹ́yìn wọ̀nyí) sì ń gbèrò láti yí ọ̀rọ̀ Allāhu padà ni.(Ìwọ Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -) sọ (fún àwọn olùsásẹ́yìn fún ogun Hudaebiyyah) pé: “Ẹ̀yin kò gbọdọ̀ tẹ̀lé wa. Báyẹn ni Allāhu ṣe sọ tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀.” Àwọn olùsásẹ́yìn náà sì ń wí pé: “Rárá (kò rí bẹ́ẹ̀), ẹ̀ ń ṣe kèéta wa ni.”2 Rárá (ẹ̀yin kò ṣe kèéta wọn, àmọ́), wọ́n kì í gbọ́ àgbọ́yé (ọ̀rọ̀) àfi díẹ̀.

Verse 16

قُل لِّلْمُخَلَّفِينَ مِنَ ٱلْأَعْرَابِ سَتُدْعَوْنَ إِلَىٰ قَوْمٍ أُو۟لِى بَأْسٍ شَدِيدٍ تُقَـٰتِلُونَهُمْ أَوْ يُسْلِمُونَ ۖ فَإِن تُطِيعُوا۟ يُؤْتِكُمُ ٱللَّهُ أَجْرًا حَسَنًا ۖ وَإِن تَتَوَلَّوْا۟ كَمَا تَوَلَّيْتُم مِّن قَبْلُ يُعَذِّبْكُمْ عَذَابًا أَلِيمًا

Transliteration qul lil'mukhallafīna mina l-aʿrābi satud'ʿawna ilā qawmin ulī basin shadīdin tuqātilūnahum aw yus'limūna fa-in tuṭīʿū yu'tikumu l-lahu ajran ḥasanan wa-in tatawallaw kamā tawallaytum min qablu yuʿadhib'kum ʿadhāban alīman

Yoruba Sọ fún àwọn olùsásẹ́yìn fún ogun nínú àwọn Lárúbáwá oko pé: “Wọ́n máa pè yín sí àwọn ènìyàn kan tí wọ́n ní agbára ogun jíjà gan-an. Ẹ máa jà wọ́n lógun tàbí kí wọ́n juwọ́ jusẹ̀ sílẹ̀ (fún ’Islām). Tí ẹ̀yin bá tẹ̀lé àṣẹ (yìí), Allāhu yóò fún yín ní ẹ̀san tó dára. Tí ẹ̀yin bá sì pẹ̀yìndà gẹ́gẹ́ bí ẹ ṣe pẹ̀yìndà ṣíwájú, (Allāhu) yó sì fi ìyà ẹlẹ́ta-eléro jẹ yín.1

Verse 17

لَّيْسَ عَلَى ٱلْأَعْمَىٰ حَرَجٌ وَلَا عَلَى ٱلْأَعْرَجِ حَرَجٌ وَلَا عَلَى ٱلْمَرِيضِ حَرَجٌ ۗ وَمَن يُطِعِ ٱللَّهَ وَرَسُولَهُۥ يُدْخِلْهُ جَنَّـٰتٍ تَجْرِى مِن تَحْتِهَا ٱلْأَنْهَـٰرُ ۖ وَمَن يَتَوَلَّ يُعَذِّبْهُ عَذَابًا أَلِيمًا

Transliteration laysa ʿalā l-aʿmā ḥarajun walā ʿalā l-aʿraji ḥarajun walā ʿalā l-marīḍi ḥarajun waman yuṭiʿi l-laha warasūlahu yud'khil'hu jannātin tajrī min taḥtihā l-anhāru waman yatawalla yuʿadhib'hu ʿadhāban alīman

Yoruba Kò sí ẹ̀ṣẹ̀ fún afọ́jú, kò sí ẹ̀ṣẹ̀ fún arọ, kò sì sí ẹ̀ṣẹ̀ fún aláìsàn (tí wọn kò bá lọ sójú ogun). Ẹnikẹ́ni tí ó bá tẹ̀lé ti Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀, (Allāhu) yóò mú un wọ inú àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra kan, èyí tí àwọn odò ń ṣàn ní ìsàlẹ̀ rẹ̀. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì pẹ̀yìndà, Ó máa jẹ ẹ́ ní ìyà ẹlẹ́ta-eléro.

Verse 18

۞ لَّقَدْ رَضِىَ ٱللَّهُ عَنِ ٱلْمُؤْمِنِينَ إِذْ يُبَايِعُونَكَ تَحْتَ ٱلشَّجَرَةِ فَعَلِمَ مَا فِى قُلُوبِهِمْ فَأَنزَلَ ٱلسَّكِينَةَ عَلَيْهِمْ وَأَثَـٰبَهُمْ فَتْحًا قَرِيبًا

Transliteration laqad raḍiya l-lahu ʿani l-mu'minīna idh yubāyiʿūnaka taḥta l-shajarati faʿalima mā fī qulūbihim fa-anzala l-sakīnata ʿalayhim wa-athābahum fatḥan qarīban

Yoruba Dájúdájú Allāhu ti yọ́nú sí àwọn onígbàgbọ́ òdodo nígbà tí wọ́n ń ṣàdéhùn fún ọ lábẹ́ igi (pé àwọn máa dúró tì ọ́ lójú ogun Hudaebiyyah). Nítorí náà, (Allāhu) mọ ohun tí ó wà nínú ọkàn wọn. Ó sì sọ ìfọ̀kànbalẹ̀ kalẹ̀ fún wọn. Ó sì san wọ́n ní ẹ̀san ìṣẹ́gun tó súnmọ́ (ìyẹn ogun Hudaebiyyah)

Verse 19

وَمَغَانِمَ كَثِيرَةً يَأْخُذُونَهَا ۗ وَكَانَ ٱللَّهُ عَزِيزًا حَكِيمًا

Transliteration wamaghānima kathīratan yakhudhūnahā wakāna l-lahu ʿazīzan ḥakīman

Yoruba àti àwọn ọrọ̀ ogun ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ tí wọn yóò rí kó. Allāhu ń jẹ́ Alágbára, Ọlọ́gbọ́n.

Verse 20

وَعَدَكُمُ ٱللَّهُ مَغَانِمَ كَثِيرَةً تَأْخُذُونَهَا فَعَجَّلَ لَكُمْ هَـٰذِهِۦ وَكَفَّ أَيْدِىَ ٱلنَّاسِ عَنكُمْ وَلِتَكُونَ ءَايَةً لِّلْمُؤْمِنِينَ وَيَهْدِيَكُمْ صِرَٰطًا مُّسْتَقِيمًا

Transliteration waʿadakumu l-lahu maghānima kathīratan takhudhūnahā faʿajjala lakum hādhihi wakaffa aydiya l-nāsi ʿankum walitakūna āyatan lil'mu'minīna wayahdiyakum ṣirāṭan mus'taqīman

Yoruba Àti pé Allāhu ṣàdéhùn àwọn ọrọ̀ ogun ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ tí ẹ̀yin yóò rí kó fún yín. Ó sì tètè mú èyí wá fún yín. Ó tún kó àwọn ènìyàn lọ́wọ́ ró fún yín nítorí kí ó lè jẹ́ àmì kan fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo àti nítorí kí Ó lè fi ẹsẹ̀ yín rinlẹ̀ sójú ọ̀nà tààrà (’Islām).

Verse 21

وَأُخْرَىٰ لَمْ تَقْدِرُوا۟ عَلَيْهَا قَدْ أَحَاطَ ٱللَّهُ بِهَا ۚ وَكَانَ ٱللَّهُ عَلَىٰ كُلِّ شَىْءٍ قَدِيرًا

Transliteration wa-ukh'rā lam taqdirū ʿalayhā qad aḥāṭa l-lahu bihā wakāna l-lahu ʿalā kulli shayin qadīran

Yoruba Àti òmíràn tí ẹ kò lágbára lórí rẹ̀, (àmọ́ tí) Allāhu ti rọkiriká rẹ̀. Allāhu sì ń jẹ́ Alágbára lórí gbogbo n̄ǹkan.

Verse 22

وَلَوْ قَـٰتَلَكُمُ ٱلَّذِينَ كَفَرُوا۟ لَوَلَّوُا۟ ٱلْأَدْبَـٰرَ ثُمَّ لَا يَجِدُونَ وَلِيًّا وَلَا نَصِيرًا

Transliteration walaw qātalakumu alladhīna kafarū lawallawū l-adbāra thumma lā yajidūna waliyyan walā naṣīran

Yoruba Tí ó bá jẹ́ pé àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ gbógun dìde si yín ni, wọn ìbá pẹ̀yìndà (láti ságun fún yín). Lẹ́yìn náà, wọn kò níí rí aláàbò tàbí alárànṣe kan.

Verse 23

سُنَّةَ ٱللَّهِ ٱلَّتِى قَدْ خَلَتْ مِن قَبْلُ ۖ وَلَن تَجِدَ لِسُنَّةِ ٱللَّهِ تَبْدِيلًا

Transliteration sunnata l-lahi allatī qad khalat min qablu walan tajida lisunnati l-lahi tabdīlan

Yoruba Ìṣe Allāhu, èyí tó ti ṣẹlẹ̀ ṣíwájú (ni èyí). O ò sì níí rí ìyípadà fún ìṣe Allāhu (lórí àwọn ọ̀tá Rẹ̀).

Verse 24

وَهُوَ ٱلَّذِى كَفَّ أَيْدِيَهُمْ عَنكُمْ وَأَيْدِيَكُمْ عَنْهُم بِبَطْنِ مَكَّةَ مِنۢ بَعْدِ أَنْ أَظْفَرَكُمْ عَلَيْهِمْ ۚ وَكَانَ ٱللَّهُ بِمَا تَعْمَلُونَ بَصِيرًا

Transliteration wahuwa alladhī kaffa aydiyahum ʿankum wa-aydiyakum ʿanhum bibaṭni makkata min baʿdi an aẓfarakum ʿalayhim wakāna l-lahu bimā taʿmalūna baṣīran

Yoruba Òun sì ni Ẹni tí Ó kó wọn lọ́wọ́ ró fún yín. Ó sì kó ẹ̀yin náà lọ́wọ́ ró fún wọn nínú ìlú Mọkkah lẹ́yìn ìgbà tí Ó ti fi yín borí wọn. Allāhu sì ń jẹ́ Olùríran nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.

Verse 25

هُمُ ٱلَّذِينَ كَفَرُوا۟ وَصَدُّوكُمْ عَنِ ٱلْمَسْجِدِ ٱلْحَرَامِ وَٱلْهَدْىَ مَعْكُوفًا أَن يَبْلُغَ مَحِلَّهُۥ ۚ وَلَوْلَا رِجَالٌ مُّؤْمِنُونَ وَنِسَآءٌ مُّؤْمِنَـٰتٌ لَّمْ تَعْلَمُوهُمْ أَن تَطَـُٔوهُمْ فَتُصِيبَكُم مِّنْهُم مَّعَرَّةٌۢ بِغَيْرِ عِلْمٍ ۖ لِّيُدْخِلَ ٱللَّهُ فِى رَحْمَتِهِۦ مَن يَشَآءُ ۚ لَوْ تَزَيَّلُوا۟ لَعَذَّبْنَا ٱلَّذِينَ كَفَرُوا۟ مِنْهُمْ عَذَابًا أَلِيمًا

Transliteration humu alladhīna kafarū waṣaddūkum ʿani l-masjidi l-ḥarāmi wal-hadya maʿkūfan an yablugha maḥillahu walawlā rijālun mu'minūna wanisāon mu'minātun lam taʿlamūhum an taṭaūhum fatuṣībakum min'hum maʿarratun bighayri ʿil'min liyud'khila l-lahu fī raḥmatihi man yashāu law tazayyalū laʿadhabnā alladhīna kafarū min'hum ʿadhāban alīman

Yoruba Àwọn (ọ̀ṣẹbọ) ni àwọn tó ṣàì gbàgbọ́, tí wọ́n ṣẹ yín lórí kúrò ní Mọ́sálásí Haram, tí wọ́n tún de ẹran ọrẹ mọ́lẹ̀ kí ó má lè dé àyè rẹ̀. Tí kì í bá ṣe ti àwọn ọkùnrin (tí wọ́n ti di) onígbàgbọ́ òdodo àti àwọn obìnrin (tí wọ́n ti di) onígbàgbọ́ òdodo (nínú ìlú Mọkkah), tí ẹ̀yin kò sì mọ̀ wọ́n, kí ẹ̀yin má lọ pa wọ́n, kí ẹ̀yin má lọ fara kó ẹ̀ṣẹ̀ láti ara wọn nípasẹ̀ àìmọ̀, (Allāhu ìbá tí ko yín lọ́wọ́ ró fún wọn. Allāhu ko yín lọ́wọ́ ró fún wọn sẹ́) nítorí kí Ó lè fi ẹni tí ó bá fẹ́ sínú ìkẹ́ Rẹ̀. Tí ó bá jẹ́ pé wọ́n wà ní ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni (onígbàgbọ́ òdodo lọ́tọ̀, aláìgbàgbọ́ lọ́tọ̀), Àwa ìbá jẹ àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ nínú wọn ní ìyà ẹlẹ́ta-eléro.

Verse 26

إِذْ جَعَلَ ٱلَّذِينَ كَفَرُوا۟ فِى قُلُوبِهِمُ ٱلْحَمِيَّةَ حَمِيَّةَ ٱلْجَـٰهِلِيَّةِ فَأَنزَلَ ٱللَّهُ سَكِينَتَهُۥ عَلَىٰ رَسُولِهِۦ وَعَلَى ٱلْمُؤْمِنِينَ وَأَلْزَمَهُمْ كَلِمَةَ ٱلتَّقْوَىٰ وَكَانُوٓا۟ أَحَقَّ بِهَا وَأَهْلَهَا ۚ وَكَانَ ٱللَّهُ بِكُلِّ شَىْءٍ عَلِيمًا

Transliteration idh jaʿala alladhīna kafarū fī qulūbihimu l-ḥamiyata ḥamiyyata l-jāhiliyati fa-anzala l-lahu sakīnatahu ʿalā rasūlihi waʿalā l-mu'minīna wa-alzamahum kalimata l-taqwā wakānū aḥaqqa bihā wa-ahlahā wakāna l-lahu bikulli shayin ʿalīman

Yoruba (Rántí) nígbà tí àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ kó ìgbónára sínú ọkàn wọn ní ìgbónára ti ìgbà àìmọ̀kan, Allāhu sì sọ ìfọ̀kànbalẹ̀ kalẹ̀ fún Òjíṣẹ́ Rẹ̀ àti àwọn onígbàgbọ́ òdodo. Ó sì jẹ́ kí ọ̀rọ̀ ìbẹ̀rù (Rẹ̀) wà pẹ̀lú wọn; Wọ́n ní ẹ̀tọ́ sí i jùlọ, àwọn ni wọ́n sì ni ín. Allāhu sì ni Onímọ̀ nípa gbogbo n̄ǹkan.

Verse 27

لَّقَدْ صَدَقَ ٱللَّهُ رَسُولَهُ ٱلرُّءْيَا بِٱلْحَقِّ ۖ لَتَدْخُلُنَّ ٱلْمَسْجِدَ ٱلْحَرَامَ إِن شَآءَ ٱللَّهُ ءَامِنِينَ مُحَلِّقِينَ رُءُوسَكُمْ وَمُقَصِّرِينَ لَا تَخَافُونَ ۖ فَعَلِمَ مَا لَمْ تَعْلَمُوا۟ فَجَعَلَ مِن دُونِ ذَٰلِكَ فَتْحًا قَرِيبًا

Transliteration laqad ṣadaqa l-lahu rasūlahu l-ru'yā bil-ḥaqi latadkhulunna l-masjida l-ḥarāma in shāa l-lahu āminīna muḥalliqīna ruūsakum wamuqaṣṣirīna lā takhāfūna faʿalima mā lam taʿlamū fajaʿala min dūni dhālika fatḥan qarīban

Yoruba Dájúdájú Allāhu ti sọ àlá Òjíṣẹ́ Rẹ̀ di òdodo pé - tí Allāhu bá fẹ́ - dájúdájú ẹ̀yin yóò wọ inú Mọ́sálásí Haram ní ẹni ìfàyàbalẹ̀, ní ẹni tí ó máa fá irun orí yín, tí ẹ sì máa gé irun (orí yín mọ́lẹ̀), tí kò níí sí ìpáyà fún yín. Nítorí náà, (Allāhu) mọ ohun tí ẹ̀yin kò mọ̀. Yàtọ̀ sí ìyẹn, Ó tún ṣe ìṣẹ́gun tó súnmọ́ (fún yín).

Verse 28

هُوَ ٱلَّذِىٓ أَرْسَلَ رَسُولَهُۥ بِٱلْهُدَىٰ وَدِينِ ٱلْحَقِّ لِيُظْهِرَهُۥ عَلَى ٱلدِّينِ كُلِّهِۦ ۚ وَكَفَىٰ بِٱللَّهِ شَهِيدًا

Transliteration huwa alladhī arsala rasūlahu bil-hudā wadīni l-ḥaqi liyuẓ'hirahu ʿalā l-dīni kullihi wakafā bil-lahi shahīdan

Yoruba (Allāhu) Òun ni Ẹni tí Ó fi ìmọ̀nà àti ẹ̀sìn òdodo (’Islām) rán Òjíṣẹ́ Rẹ̀ nítorí kí Ó lè fi borí gbogbo ẹ̀sìn (mìíràn) pátápátá. Allāhu sì tó ní Ẹlẹ́rìí.

Verse 29

مُّحَمَّدٌ رَّسُولُ ٱللَّهِ ۚ وَٱلَّذِينَ مَعَهُۥٓ أَشِدَّآءُ عَلَى ٱلْكُفَّارِ رُحَمَآءُ بَيْنَهُمْ ۖ تَرَىٰهُمْ رُكَّعًا سُجَّدًا يَبْتَغُونَ فَضْلًا مِّنَ ٱللَّهِ وَرِضْوَٰنًا ۖ سِيمَاهُمْ فِى وُجُوهِهِم مِّنْ أَثَرِ ٱلسُّجُودِ ۚ ذَٰلِكَ مَثَلُهُمْ فِى ٱلتَّوْرَىٰةِ ۚ وَمَثَلُهُمْ فِى ٱلْإِنجِيلِ كَزَرْعٍ أَخْرَجَ شَطْـَٔهُۥ فَـَٔازَرَهُۥ فَٱسْتَغْلَظَ فَٱسْتَوَىٰ عَلَىٰ سُوقِهِۦ يُعْجِبُ ٱلزُّرَّاعَ لِيَغِيظَ بِهِمُ ٱلْكُفَّارَ ۗ وَعَدَ ٱللَّهُ ٱلَّذِينَ ءَامَنُوا۟ وَعَمِلُوا۟ ٱلصَّـٰلِحَـٰتِ مِنْهُم مَّغْفِرَةً وَأَجْرًا عَظِيمًۢا

Transliteration muḥammadun rasūlu l-lahi wa-alladhīna maʿahu ashiddāu ʿalā l-kufāri ruḥamāu baynahum tarāhum rukkaʿan sujjadan yabtaghūna faḍlan mina l-lahi wariḍ'wānan sīmāhum fī wujūhihim min athari l-sujūdi dhālika mathaluhum fī l-tawrāti wamathaluhum fī l-injīli kazarʿin akhraja shaṭahu faāzarahu fa-is'taghlaẓa fa-is'tawā ʿalā sūqihi yuʿ'jibu l-zurāʿa liyaghīẓa bihimu l-kufāra waʿada l-lahu alladhīna āmanū waʿamilū l-ṣāliḥāti min'hum maghfiratan wa-ajran ʿaẓīman

Yoruba Muhammad ni Òjíṣẹ́ Allāhu. Àwọn tó wà pẹ̀lú rẹ̀, wọ́n le mọ́ àwọn aláìgbàgbọ́, aláàánú sì ni wọ́n láààrin ara wọn. O máa rí wọn ní olùdáwọ́tẹ-orúnkún àti olùforíkanlẹ̀ (lórí ìrun), tí wọ́n ń wá oore àjùlọ àti ìyọ́nú láti ọ̀dọ̀ Allāhu. Àmì wọn wà ní ojú wọn níbi orípa ìforíkanlẹ̀. Ìyẹn ni àpèjúwe wọn nínú Taorāh àti àpèjúwe wọn nínú ’Injīl, (wọ́n dà) gẹ́gẹ́ bí irúgbìn kan tó yọ ẹ̀ka rẹ̀ jáde. Lẹ́yìn náà, ó fún un lágbára, ó nípọn, ó sì dúró gbagidi lórí igi rẹ̀. Ó sì ń jọ àwọn àgbẹ̀ lójú. (Allāhu fi àyè gba Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - àti àwọn Sọhābah rẹ̀) nítorí kí Ó lè fi wọ́n ṣe ohun ìbínú fún àwọn aláìgbàgbọ́. Allāhu ṣàdéhùn àforíjìn àti ẹ̀san ńlá fún àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe àwọn iṣẹ́ rere nínú wọn.

Read Surah Al-Fath in another language

All languages

All 114 surahs in Yoruba: the Qur’an in Yoruba.

Learn it in MyDugsi

Yoruba translation: Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni, from Quran.com. Transliteration: Quran.com. Recitation: Mishary Alafasy, from EveryAyah.com. MyDugsi is a learning aid, not a replacement for a qualified teacher.