Surah Al-Buruj in Yoruba: translation and audio
Surah 85 · البروج · The Mansions of the Stars · 22 verses
Surah Al-Buruj verse by verse: the Arabic with a recitation you can repeat, the transliteration, and the Yoruba translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni. For the meaning of every word, see Surah Al-Buruj word by word in English.
Verse 1
وَٱلسَّمَآءِ ذَاتِ ٱلْبُرُوجِ
Transliteration wal-samāi dhāti l-burūji
Yoruba (Allāhu) fi sánmọ̀ tí àwọn ibùsọ̀ (òòrùn, òṣùpá àti àwọn ìràwọ̀) wà nínú rẹ̀ búra.
Verse 2
وَٱلْيَوْمِ ٱلْمَوْعُودِ
Transliteration wal-yawmi l-mawʿūdi
Yoruba Ó tún fi ọjọ́ tí wọ́n ṣe ní àdéhùn (ìyẹn Ọjọ́ Àjíǹde) búra.
Verse 3
وَشَاهِدٍ وَمَشْهُودٍ
Transliteration washāhidin wamashhūdin
Yoruba Ó tún fi olùjẹ́rìí àti ohun tó jẹ́rìí sí búra.
Verse 4
قُتِلَ أَصْحَـٰبُ ٱلْأُخْدُودِ
Transliteration qutila aṣḥābu l-ukh'dūdi
Yoruba A ṣẹ́bi lé àwọn tó gbẹ́ kòtò (iná),
Verse 5
ٱلنَّارِ ذَاتِ ٱلْوَقُودِ
Transliteration al-nāri dhāti l-waqūdi
Yoruba (ìyẹn) iná tí wọ́n ń fi igi kò (nínú kòtò).
Verse 6
إِذْ هُمْ عَلَيْهَا قُعُودٌ
Transliteration idh hum ʿalayhā quʿūdun
Yoruba (Rántí) nígbà tí wọ́n jókòó sí ìtòsí rẹ̀.
Verse 7
وَهُمْ عَلَىٰ مَا يَفْعَلُونَ بِٱلْمُؤْمِنِينَ شُهُودٌ
Transliteration wahum ʿalā mā yafʿalūna bil-mu'minīna shuhūdun
Yoruba Wọ́n sì ń wo ohun tí wọ́n ń ṣe fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo.
Verse 8
وَمَا نَقَمُوا۟ مِنْهُمْ إِلَّآ أَن يُؤْمِنُوا۟ بِٱللَّهِ ٱلْعَزِيزِ ٱلْحَمِيدِ
Transliteration wamā naqamū min'hum illā an yu'minū bil-lahi l-ʿazīzi l-ḥamīdi
Yoruba Wọn kò rí àlèébù kan (wọn kò sì kórira kiní kan) lára wọn bí kò ṣe pé, wọ́n ní ìgbàgbọ́ òdodo nínú Allāhu, Alágbára, Ẹlẹ́yìn,
Verse 9
ٱلَّذِى لَهُۥ مُلْكُ ٱلسَّمَـٰوَٰتِ وَٱلْأَرْضِ ۚ وَٱللَّهُ عَلَىٰ كُلِّ شَىْءٍ شَهِيدٌ
Transliteration alladhī lahu mul'ku l-samāwāti wal-arḍi wal-lahu ʿalā kulli shayin shahīdun
Yoruba Ẹni tí Ó ni ìjọba àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Allāhu sì ni Ẹlẹ́rìí lórí gbogbo n̄ǹkan.
Verse 10
إِنَّ ٱلَّذِينَ فَتَنُوا۟ ٱلْمُؤْمِنِينَ وَٱلْمُؤْمِنَـٰتِ ثُمَّ لَمْ يَتُوبُوا۟ فَلَهُمْ عَذَابُ جَهَنَّمَ وَلَهُمْ عَذَابُ ٱلْحَرِيقِ
Transliteration inna alladhīna fatanū l-mu'minīna wal-mu'mināti thumma lam yatūbū falahum ʿadhābu jahannama walahum ʿadhābu l-ḥarīqi
Yoruba Dájúdájú àwọn tó fi ìnira kan àwọn onígbàgbọ́ òdodo lọ́kùnrin àti àwọn onígbàgbọ́ òdodo lóbìnrin, lẹ́yìn náà tí wọn kò ronú pìwàdà, ìyà iná Jahanamọ ń bẹ fún wọn. Ìyà iná tó ń jó sì wà fún wọn.
Verse 11
إِنَّ ٱلَّذِينَ ءَامَنُوا۟ وَعَمِلُوا۟ ٱلصَّـٰلِحَـٰتِ لَهُمْ جَنَّـٰتٌ تَجْرِى مِن تَحْتِهَا ٱلْأَنْهَـٰرُ ۚ ذَٰلِكَ ٱلْفَوْزُ ٱلْكَبِيرُ
Transliteration inna alladhīna āmanū waʿamilū l-ṣāliḥāti lahum jannātun tajrī min taḥtihā l-anhāru dhālika l-fawzu l-kabīru
Yoruba Dájúdájú àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe àwọn iṣẹ́ rere, tiwọn ni àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra kan, tí àwọn odò ń ṣàn ní ìsàlẹ̀ rẹ̀. Ìyẹn sì ni èrèǹjẹ ńlá.
Verse 12
إِنَّ بَطْشَ رَبِّكَ لَشَدِيدٌ
Transliteration inna baṭsha rabbika lashadīdun
Yoruba Dájúdájú ìgbámú ti Olúwa rẹ mà le.
Verse 13
إِنَّهُۥ هُوَ يُبْدِئُ وَيُعِيدُ
Transliteration innahu huwa yub'di-u wayuʿīdu
Yoruba Dájúdájú Òun ni Ó pìlẹ̀ (ẹ̀dá), Ó sì máa dá (ẹ̀dá) padà (fún àjíǹde).
Verse 14
وَهُوَ ٱلْغَفُورُ ٱلْوَدُودُ
Transliteration wahuwa l-ghafūru l-wadūdu
Yoruba Òun ni Aláforíjìn, Olólùfẹ́ (ẹ̀dá),
Verse 15
ذُو ٱلْعَرْشِ ٱلْمَجِيدُ
Transliteration dhū l-ʿarshi l-majīdu
Yoruba Òun l’Ó ni Ìtẹ́-ọlá, Ológo (Ẹni-ọ̀wọ̀ jùlọ),
Verse 16
فَعَّالٌ لِّمَا يُرِيدُ
Transliteration faʿʿālun limā yurīdu
Yoruba Olùṣe-ohun-t’Ó-bá-fẹ́.
Verse 17
هَلْ أَتَىٰكَ حَدِيثُ ٱلْجُنُودِ
Transliteration hal atāka ḥadīthu l-junūdi
Yoruba Ṣebí ìró àwọn ọmọ ogun ti dé ọ̀dọ̀ rẹ,
Verse 18
فِرْعَوْنَ وَثَمُودَ
Transliteration fir'ʿawna wathamūda
Yoruba (ọmọ ogun) Fir‘aon àti (ìjọ) Thamūd?
Verse 19
بَلِ ٱلَّذِينَ كَفَرُوا۟ فِى تَكْذِيبٍ
Transliteration bali alladhīna kafarū fī takdhībin
Yoruba Síbẹ̀síbẹ̀ àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ sì ń pe òdodo ní irọ́.
Verse 20
وَٱللَّهُ مِن وَرَآئِهِم مُّحِيطٌۢ
Transliteration wal-lahu min warāihim muḥīṭun
Yoruba Allāhu sì yí wọn ká lẹ́yìn wọn.
Verse 21
بَلْ هُوَ قُرْءَانٌ مَّجِيدٌ
Transliteration bal huwa qur'ānun majīdun
Yoruba Àmọ́ sá, ohun (tí A fi ránṣẹ́ sí ọ ni) al-Ƙur’ān alápọ̀n-ọ́nlé,
Verse 22
فِى لَوْحٍ مَّحْفُوظٍۭ
Transliteration fī lawḥin maḥfūẓin
Yoruba tí ó wà nínú wàláà tí wọ́n ń ṣọ́.
Read Surah Al-Buruj in another language
- English (word by word)
- Albanian
- Amazigh
- Amharic
- Assamese
- Azerbaijani
- Bambara
- Bangla
- Bosnian
- Bulgarian
- Chechen
- Chinese
- Czech
- Dari
- Dhivehi
- Dutch
- Finnish
- French
- German
- Gujarati
- Hausa
- Hebrew
- Hindi
- Indonesian
- Italian
- Japanese
- Kannada
- Kazakh
- Khmer
- Kinyarwanda
- Korean
- Kurdish
- Luganda
- Malay
- Malayalam
- Maranao
- Marathi
- Nepali
- Norwegian
- Oromo
- Pashto
- Persian
- Polish
- Portuguese
- Romanian
- Russian
- Sindhi
- Sinhala
- Somali
- Spanish
- Swahili
- Swedish
- Tagalog
- Tajik
- Tamil
- Tatar
- Telugu
- Thai
- Turkish
- Ukrainian
- Urdu
- Uyghur
- Uzbek
- Vietnamese
- Yao
All 114 surahs in Yoruba: the Qur’an in Yoruba.
Yoruba translation: Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni, from Quran.com. Transliteration: Quran.com. Recitation: Mishary Alafasy, from EveryAyah.com. MyDugsi is a learning aid, not a replacement for a qualified teacher.