Surah Qaf in Yoruba: translation and audio
Surah 50 · ق · The Letter "Qaf" · 45 verses
Surah Qaf verse by verse: the Arabic with a recitation you can repeat, the transliteration, and the Yoruba translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni. For the meaning of every word, see Surah Qaf word by word in English.
Verse 1
قٓ ۚ وَٱلْقُرْءَانِ ٱلْمَجِيدِ
Transliteration qaf wal-qur'āni l-majīdi
Yoruba Ƙọ̄f. (Allāhu ló mọ ohun tí Ó gbàlérò pẹ̀lú àwọn háràfí náà.)(Allāhu fi) al-Ƙur’ān alápọ̀n-ọ́nlé búra.
Verse 2
بَلْ عَجِبُوٓا۟ أَن جَآءَهُم مُّنذِرٌ مِّنْهُمْ فَقَالَ ٱلْكَـٰفِرُونَ هَـٰذَا شَىْءٌ عَجِيبٌ
Transliteration bal ʿajibū an jāahum mundhirun min'hum faqāla l-kāfirūna hādhā shayon ʿajībun
Yoruba Ṣùgbọ́n wọ́n ṣèèmọ̀ nítorí pé olùkìlọ̀ kan wá bá wọn láti ààrin ara wọn. Àwọn aláìgbàgbọ́ sì wí pé: “Èyí ni ohun ìyanu.”
Verse 3
أَءِذَا مِتْنَا وَكُنَّا تُرَابًا ۖ ذَٰلِكَ رَجْعٌۢ بَعِيدٌ
Transliteration a-idhā mit'nā wakunnā turāban dhālika rajʿun baʿīdun
Yoruba Ṣé nígbà tí a bá ti kú, tí a ti di erùpẹ̀ (ni a óò tún jí dìde padà). Ìyẹn ni ìdápadà tó jìnnà (sí n̄ǹkan tí ó lè ṣẹlẹ̀).
Verse 4
قَدْ عَلِمْنَا مَا تَنقُصُ ٱلْأَرْضُ مِنْهُمْ ۖ وَعِندَنَا كِتَـٰبٌ حَفِيظٌۢ
Transliteration qad ʿalim'nā mā tanquṣu l-arḍu min'hum waʿindanā kitābun ḥafīẓun
Yoruba Dájúdájú A ti mọ ohun tí ilẹ̀ ń mú jẹ nínú wọn. Tírà (iṣẹ́ ẹ̀dá) tí wọ́n ń ṣọ́ sì wà ní ọ̀dọ̀ Wa.
Verse 5
بَلْ كَذَّبُوا۟ بِٱلْحَقِّ لَمَّا جَآءَهُمْ فَهُمْ فِىٓ أَمْرٍ مَّرِيجٍ
Transliteration bal kadhabū bil-ḥaqi lammā jāahum fahum fī amrin marījin
Yoruba Síbẹ̀síbẹ̀ wọ́n pe òdodo (al-Ƙur’ān) ní irọ́ nígbà tí ó dé bá wọn. Nítorí náà, wọ́n ti wà nínú ìdààmú.
Verse 6
أَفَلَمْ يَنظُرُوٓا۟ إِلَى ٱلسَّمَآءِ فَوْقَهُمْ كَيْفَ بَنَيْنَـٰهَا وَزَيَّنَّـٰهَا وَمَا لَهَا مِن فُرُوجٍ
Transliteration afalam yanẓurū ilā l-samāi fawqahum kayfa banaynāhā wazayyannāhā wamā lahā min furūjin
Yoruba Ṣé wọn kò wo sánmọ̀ òkè wọn bí A ti ṣe mọ ọ́n pa àti (bí) A ti ṣe ṣe é ní ọ̀ṣọ́, tí kò sì sí àlàfo sísán kan lára rẹ̀?
Verse 7
وَٱلْأَرْضَ مَدَدْنَـٰهَا وَأَلْقَيْنَا فِيهَا رَوَٰسِىَ وَأَنۢبَتْنَا فِيهَا مِن كُلِّ زَوْجٍۭ بَهِيجٍ
Transliteration wal-arḍa madadnāhā wa-alqaynā fīhā rawāsiya wa-anbatnā fīhā min kulli zawjin bahījin
Yoruba Àti pé ilẹ̀, A tẹ́ ẹ pẹrẹsẹ. A sì ju àwọn àpáta tó dúró gbagidi sínú rẹ̀. A sì mú oríṣiríṣi irúgbìn tó dára hù jáde láti inú rẹ̀.
Verse 8
تَبْصِرَةً وَذِكْرَىٰ لِكُلِّ عَبْدٍ مُّنِيبٍ
Transliteration tabṣiratan wadhik'rā likulli ʿabdin munībin
Yoruba (Ó jẹ́) àríwòye àti ìrántí fún gbogbo ẹrúsìn tó ń ṣẹ́rí padà (síbi òdodo).
Verse 9
وَنَزَّلْنَا مِنَ ٱلسَّمَآءِ مَآءً مُّبَـٰرَكًا فَأَنۢبَتْنَا بِهِۦ جَنَّـٰتٍ وَحَبَّ ٱلْحَصِيدِ
Transliteration wanazzalnā mina l-samāi māan mubārakan fa-anbatnā bihi jannātin waḥabba l-ḥaṣīdi
Yoruba A ń sọ omi ìbùkún kalẹ̀ láti sánmọ̀. A sì ń fi mú àwọn ọgbà oko àti àwọn èso tí wọ́n ń kórè rẹ̀ hù jáde.
Verse 10
وَٱلنَّخْلَ بَاسِقَـٰتٍ لَّهَا طَلْعٌ نَّضِيدٌ
Transliteration wal-nakhla bāsiqātin lahā ṭalʿun naḍīdun
Yoruba (A tún mú) igi dàbínù hù ga, tí àwọn èso orí rẹ̀ so jìgbìnnì.
Verse 11
رِّزْقًا لِّلْعِبَادِ ۖ وَأَحْيَيْنَا بِهِۦ بَلْدَةً مَّيْتًا ۚ كَذَٰلِكَ ٱلْخُرُوجُ
Transliteration riz'qan lil'ʿibādi wa-aḥyaynā bihi baldatan maytan kadhālika l-khurūju
Yoruba Arísìkí ni fún àwọn ẹrú (Allāhu). A sì ń fi sọ òkú ilẹ̀ di àyè. Báyẹn ni ìjáde ẹ̀dá (láti inú sàréè yó ṣe rí).
Verse 12
كَذَّبَتْ قَبْلَهُمْ قَوْمُ نُوحٍ وَأَصْحَـٰبُ ٱلرَّسِّ وَثَمُودُ
Transliteration kadhabat qablahum qawmu nūḥin wa-aṣḥābu l-rasi wathamūdu
Yoruba Àwọn ènìyàn (Ànábì) Nūh, àwọn ènìyàn Rass àti àwọn (ènìyàn) Thamūd pe òdodo ní irọ́ ṣíwájú wọn.
Verse 13
وَعَادٌ وَفِرْعَوْنُ وَإِخْوَٰنُ لُوطٍ
Transliteration waʿādun wafir'ʿawnu wa-ikh'wānu lūṭin
Yoruba Àti àwọn ‘Ād, Fir‘aon àti àwọn ọmọ ìyá (Ànábì) Lūt,
Verse 14
وَأَصْحَـٰبُ ٱلْأَيْكَةِ وَقَوْمُ تُبَّعٍ ۚ كُلٌّ كَذَّبَ ٱلرُّسُلَ فَحَقَّ وَعِيدِ
Transliteration wa-aṣḥābu l-aykati waqawmu tubbaʿin kullun kadhaba l-rusula faḥaqqa waʿīdi
Yoruba àti àwọn ará ’Aekah àti àwọn ìjọ Tubba‘u; gbogbo wọn pe àwọn Òjíṣẹ́ ní òpùrọ́. Nítorí náà, ìlérí Mi sì kò (lórí wọn).
Verse 15
أَفَعَيِينَا بِٱلْخَلْقِ ٱلْأَوَّلِ ۚ بَلْ هُمْ فِى لَبْسٍ مِّنْ خَلْقٍ جَدِيدٍ
Transliteration afaʿayīnā bil-khalqi l-awali bal hum fī labsin min khalqin jadīdin
Yoruba Ǹjẹ́ ìṣẹ̀dá àkọ́kọ́ kó agara bá Wa bí? Rárá, wọ́n wà nínú iyèméjì (àti ìrújú) nípa ìṣẹ̀dá (wọn) ní ọ̀tun ni.
Verse 16
وَلَقَدْ خَلَقْنَا ٱلْإِنسَـٰنَ وَنَعْلَمُ مَا تُوَسْوِسُ بِهِۦ نَفْسُهُۥ ۖ وَنَحْنُ أَقْرَبُ إِلَيْهِ مِنْ حَبْلِ ٱلْوَرِيدِ
Transliteration walaqad khalaqnā l-insāna wanaʿlamu mā tuwaswisu bihi nafsuhu wanaḥnu aqrabu ilayhi min ḥabli l-warīdi
Yoruba Dájúdájú A ṣẹ̀dá ènìyàn. A sì mọ ohun tí ẹ̀mí rẹ̀ ń sọ fún un ní ròyíròyí. Àwa sì súnmọ́ ọn ju isan ọrùn rẹ̀.1
Verse 17
إِذْ يَتَلَقَّى ٱلْمُتَلَقِّيَانِ عَنِ ٱلْيَمِينِ وَعَنِ ٱلشِّمَالِ قَعِيدٌ
Transliteration idh yatalaqqā l-mutalaqiyāni ʿani l-yamīni waʿani l-shimāli qaʿīdun
Yoruba (Rántí) nígbà tí (mọlāika) àwọn olùgbọ̀rọ̀-sílẹ̀ méjì bá bẹ̀rẹ̀sí gba ọ̀rọ̀ (sílẹ̀), tí ọ̀kan jókòó sí ọ̀tún, tí ọ̀kan jókòó sí òsì.
Verse 18
مَّا يَلْفِظُ مِن قَوْلٍ إِلَّا لَدَيْهِ رَقِيبٌ عَتِيدٌ
Transliteration mā yalfiẓu min qawlin illā ladayhi raqībun ʿatīdun
Yoruba (Ẹnì kan) kò sì níí sọ ọ̀rọ̀ kan àyàfi kí ẹ̀ṣọ́ kan ti wà níkàlẹ̀ pẹ̀lú rẹ̀ (fún àkọsílẹ̀ rẹ̀).
Verse 19
وَجَآءَتْ سَكْرَةُ ٱلْمَوْتِ بِٱلْحَقِّ ۖ ذَٰلِكَ مَا كُنتَ مِنْهُ تَحِيدُ
Transliteration wajāat sakratu l-mawti bil-ḥaqi dhālika mā kunta min'hu taḥīdu
Yoruba Àti pé ìpọ́kàkà ikú yóò dé láti fi òdodo ọ̀run rinlẹ̀. Ìyẹn ni ohun tí ìwọ ń sá fún.
Verse 20
وَنُفِخَ فِى ٱلصُّورِ ۚ ذَٰلِكَ يَوْمُ ٱلْوَعِيدِ
Transliteration wanufikha fī l-ṣūri dhālika yawmu l-waʿīdi
Yoruba Wọ́n á fọn fèrè oníwo fún àjíǹde. Ìyẹn ni ọjọ́ ìlérí náà.
Verse 21
وَجَآءَتْ كُلُّ نَفْسٍ مَّعَهَا سَآئِقٌ وَشَهِيدٌ
Transliteration wajāat kullu nafsin maʿahā sāiqun washahīdun
Yoruba Ẹ̀mí kọ̀ọ̀kan yóò wá pẹ̀lú olùdarí kan àti ẹlẹ́rìí kan (nínú àwọn mọlāika).
Verse 22
لَّقَدْ كُنتَ فِى غَفْلَةٍ مِّنْ هَـٰذَا فَكَشَفْنَا عَنكَ غِطَآءَكَ فَبَصَرُكَ ٱلْيَوْمَ حَدِيدٌ
Transliteration laqad kunta fī ghaflatin min hādhā fakashafnā ʿanka ghiṭāaka fabaṣaruka l-yawma ḥadīdun
Yoruba Dájúdájú ìwọ ti wà nínú ìgbàgbéra níbi èyí. A sì ti ṣí èbìbò (ojú) rẹ kúrò fún ọ báyìí. Nítorí náà, ìríran rẹ yóò ríran kedere ní òní.
Verse 23
وَقَالَ قَرِينُهُۥ هَـٰذَا مَا لَدَىَّ عَتِيدٌ
Transliteration waqāla qarīnuhu hādhā mā ladayya ʿatīdun
Yoruba (Mọlāika) alábàárìn rẹ̀ yóò sọ pé: “Èyí ti wà nílẹ̀ ni ohun tí ń bẹ ní ọ̀dọ̀ mi (gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ iṣẹ́ rẹ̀).”
Verse 24
أَلْقِيَا فِى جَهَنَّمَ كُلَّ كَفَّارٍ عَنِيدٍ
Transliteration alqiyā fī jahannama kulla kaffārin ʿanīdin
Yoruba Ẹ̀yin mọlāika méjèèjì,ẹ ju gbogbo aláìgbàgbọ́ olóríkunkun sínú iná Jahanamọ.
Verse 25
مَّنَّاعٍ لِّلْخَيْرِ مُعْتَدٍ مُّرِيبٍ
Transliteration mannāʿin lil'khayri muʿ'tadin murībin
Yoruba (Ẹ ju) ẹni tí ó dènà iṣẹ́ rere, alákọyọ, oníyèméjì (sínú Iná).
Verse 26
ٱلَّذِى جَعَلَ مَعَ ٱللَّهِ إِلَـٰهًا ءَاخَرَ فَأَلْقِيَاهُ فِى ٱلْعَذَابِ ٱلشَّدِيدِ
Transliteration alladhī jaʿala maʿa l-lahi ilāhan ākhara fa-alqiyāhu fī l-ʿadhābi l-shadīdi
Yoruba Ẹni tó mú ọlọ́hun mìíràn mọ́ Allāhu, ẹ jù ú sínú ìyà líle.
Verse 27
۞ قَالَ قَرِينُهُۥ رَبَّنَا مَآ أَطْغَيْتُهُۥ وَلَـٰكِن كَانَ فِى ضَلَـٰلٍۭ بَعِيدٍ
Transliteration qāla qarīnuhu rabbanā mā aṭghaytuhu walākin kāna fī ḍalālin baʿīdin
Yoruba (Èṣù) alábàárìn rẹ̀ yóò wí pé: “Olúwa wa, èmi kọ́ ni mo mú un tayọ ẹnu-ààlà, ṣùgbọ́n ó ti wà nínú ìṣìnà tó jìnnà (sí òdodo) tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀.”
Verse 28
قَالَ لَا تَخْتَصِمُوا۟ لَدَىَّ وَقَدْ قَدَّمْتُ إِلَيْكُم بِٱلْوَعِيدِ
Transliteration qāla lā takhtaṣimū ladayya waqad qaddamtu ilaykum bil-waʿīdi
Yoruba (Allāhu) yóò sọ pé: “Ẹ má se ṣàríyànjiyàn lọ́dọ̀ Mi. Mo kúkú ti ṣe ìlérí fún yín ṣíwájú.
Verse 29
مَا يُبَدَّلُ ٱلْقَوْلُ لَدَىَّ وَمَآ أَنَا۠ بِظَلَّـٰمٍ لِّلْعَبِيدِ
Transliteration mā yubaddalu l-qawlu ladayya wamā anā biẓallāmin lil'ʿabīdi
Yoruba Wọn kò sì lè yí ọ̀rọ̀ náà padà ní ọ̀dọ̀ Mi. Èmi kò sì níí ṣe àbòsí sí àwọn ẹrú Mi.”
Verse 30
يَوْمَ نَقُولُ لِجَهَنَّمَ هَلِ ٱمْتَلَأْتِ وَتَقُولُ هَلْ مِن مَّزِيدٍ
Transliteration yawma naqūlu lijahannama hali im'talati wataqūlu hal min mazīdin
Yoruba (Rántí) ọjọ́ tí A óò sọ fún iná Jahanamọ pé: Ṣèbí o ti kún?” Ó sì máa sọ pé: “Ṣèbí àfikún tún wà?”
Verse 31
وَأُزْلِفَتِ ٱلْجَنَّةُ لِلْمُتَّقِينَ غَيْرَ بَعِيدٍ
Transliteration wa-uz'lifati l-janatu lil'muttaqīna ghayra baʿīdin
Yoruba Wọ́n máa sún Ọgbà Ìdẹ̀ra mọ́ àwọn olùbẹ̀rù (Allāhu). Kò sì níí jìnnà (sí wọn).
Verse 32
هَـٰذَا مَا تُوعَدُونَ لِكُلِّ أَوَّابٍ حَفِيظٍ
Transliteration hādhā mā tūʿadūna likulli awwābin ḥafīẓin
Yoruba Èyí ni ohun tí À ń ṣe ní àdéhùn fún gbogbo olùronúpìwàdà, olùṣọ́ (òfin Allāhu).
Verse 33
مَّنْ خَشِىَ ٱلرَّحْمَـٰنَ بِٱلْغَيْبِ وَجَآءَ بِقَلْبٍ مُّنِيبٍ
Transliteration man khashiya l-raḥmāna bil-ghaybi wajāa biqalbin munībin
Yoruba Ẹnikẹ́ni tí ó bá páyà Allāhu ní ìkọ̀kọ̀, tí ó tún dé pẹ̀lú ọkàn tó ṣẹ́rí padà sí ọ̀dọ̀ Allāhu (nípa ìronúpìwàdà),
Verse 34
ٱدْخُلُوهَا بِسَلَـٰمٍ ۖ ذَٰلِكَ يَوْمُ ٱلْخُلُودِ
Transliteration ud'khulūhā bisalāmin dhālika yawmu l-khulūdi
Yoruba (A óò sọ fún wọn pé): “Ẹ wọ inú (Ọgbà Ìdẹ̀ra) pẹ̀lú àlàáfíà. Ìyẹn ni ọjọ́ gbére.”
Verse 35
لَهُم مَّا يَشَآءُونَ فِيهَا وَلَدَيْنَا مَزِيدٌ
Transliteration lahum mā yashāūna fīhā waladaynā mazīdun
Yoruba Ohun tí wọ́n ń fẹ́ wà nínú rẹ̀. Àlékún sì tún wà ní ọ̀dọ̀ Wa.
Verse 36
وَكَمْ أَهْلَكْنَا قَبْلَهُم مِّن قَرْنٍ هُمْ أَشَدُّ مِنْهُم بَطْشًا فَنَقَّبُوا۟ فِى ٱلْبِلَـٰدِ هَلْ مِن مَّحِيصٍ
Transliteration wakam ahlaknā qablahum min qarnin hum ashaddu min'hum baṭshan fanaqqabū fī l-bilādi hal min maḥīṣin
Yoruba Mélòó mélòó nínú àwọn ìjọ tí A ti parẹ́ ṣíwájú wọn. Wọ́n sì ní agbára jù wọ́n lọ. (Nígbà tí ìyà dé) wọ́n sá àsálà kiri nínú ìlú. Ǹjẹ́ ibùsásí kan wà (fún wọn bí?)
Verse 37
إِنَّ فِى ذَٰلِكَ لَذِكْرَىٰ لِمَن كَانَ لَهُۥ قَلْبٌ أَوْ أَلْقَى ٱلسَّمْعَ وَهُوَ شَهِيدٌ
Transliteration inna fī dhālika ladhik'rā liman kāna lahu qalbun aw alqā l-samʿa wahuwa shahīdun
Yoruba Dájúdájú ìrántí wà nínú ìyẹn fún ẹni tó ní ọkàn tàbí ẹni tó fi etí sílẹ̀, tó wà níbẹ̀ (pẹ̀lú ọkàn rẹ̀).
Verse 38
وَلَقَدْ خَلَقْنَا ٱلسَّمَـٰوَٰتِ وَٱلْأَرْضَ وَمَا بَيْنَهُمَا فِى سِتَّةِ أَيَّامٍ وَمَا مَسَّنَا مِن لُّغُوبٍ
Transliteration walaqad khalaqnā l-samāwāti wal-arḍa wamā baynahumā fī sittati ayyāmin wamā massanā min lughūbin
Yoruba Dájúdájú A ṣẹ̀dá àwọn sánmọ̀, ilẹ̀ àti n̄ǹkan tó wà láààrin àwọn méjèèjì fún ọjọ́ mẹ́fà. Kò sì rẹ̀ Wá rárá (áḿbọ̀sìbọ́sí pé A óò sinmi ní ọjọ́ keje).
Verse 39
فَٱصْبِرْ عَلَىٰ مَا يَقُولُونَ وَسَبِّحْ بِحَمْدِ رَبِّكَ قَبْلَ طُلُوعِ ٱلشَّمْسِ وَقَبْلَ ٱلْغُرُوبِ
Transliteration fa-iṣ'bir ʿalā mā yaqūlūna wasabbiḥ biḥamdi rabbika qabla ṭulūʿi l-shamsi waqabla l-ghurūbi
Yoruba Nítorí náà, ṣe sùúrù lórí ohun tí wọ́n ń wí. Kí o sì ṣe àfọ̀mọ́ pẹ̀lú ẹyìn fún Olúwa Rẹṣíwájú yíyọ òòrùn àti wíwọ̀ (rẹ̀).
Verse 40
وَمِنَ ٱلَّيْلِ فَسَبِّحْهُ وَأَدْبَـٰرَ ٱلسُّجُودِ
Transliteration wamina al-layli fasabbiḥ'hu wa-adbāra l-sujūdi
Yoruba Àti pé ní òru àti ni ẹ̀yìn ìrun ṣe àfọ̀mọ́ fún Un.
Verse 41
وَٱسْتَمِعْ يَوْمَ يُنَادِ ٱلْمُنَادِ مِن مَّكَانٍ قَرِيبٍ
Transliteration wa-is'tamiʿ yawma yunādi l-munādi min makānin qarībin
Yoruba Kí o sì tẹ́tí sí (ọ̀rọ̀) ọjọ́ tí olùpèpè yóò pèpè láti àyè kan tó súnmọ́.
Verse 42
يَوْمَ يَسْمَعُونَ ٱلصَّيْحَةَ بِٱلْحَقِّ ۚ ذَٰلِكَ يَوْمُ ٱلْخُرُوجِ
Transliteration yawma yasmaʿūna l-ṣayḥata bil-ḥaqi dhālika yawmu l-khurūji
Yoruba Ọjọ́ tí wọn yóò gbọ́ igbe pẹ̀lú òdodo. Ìyẹn ni ọjọ́ ìjáde ẹ̀dá (láti inú sàréè).
Verse 43
إِنَّا نَحْنُ نُحْىِۦ وَنُمِيتُ وَإِلَيْنَا ٱلْمَصِيرُ
Transliteration innā naḥnu nuḥ'yī wanumītu wa-ilaynā l-maṣīru
Yoruba Dájúdájú Àwa, Àwa l’À ń sọ ẹ̀dá di alààyè. A sì ń sọ ọ́ di òkú. Ọ̀dọ̀ Wa sì ni àbọ̀ ẹ̀dá.
Verse 44
يَوْمَ تَشَقَّقُ ٱلْأَرْضُ عَنْهُمْ سِرَاعًا ۚ ذَٰلِكَ حَشْرٌ عَلَيْنَا يَسِيرٌ
Transliteration yawma tashaqqaqu l-arḍu ʿanhum sirāʿan dhālika ḥashrun ʿalaynā yasīrun
Yoruba (Rántí) ọjọ́ tí ilẹ̀ yóò fàya pẹ́rẹpẹ̀rẹ mọ́ wọn lára, (tí wọn yóò máa) yára (jáde láti inú ilẹ̀). Ìyẹn ni àkójọ tó rọrùn fún Wa.
Verse 45
نَّحْنُ أَعْلَمُ بِمَا يَقُولُونَ ۖ وَمَآ أَنتَ عَلَيْهِم بِجَبَّارٍ ۖ فَذَكِّرْ بِٱلْقُرْءَانِ مَن يَخَافُ وَعِيدِ
Transliteration naḥnu aʿlamu bimā yaqūlūna wamā anta ʿalayhim bijabbārin fadhakkir bil-qur'āni man yakhāfu waʿīdi
Yoruba Àwa nímọ̀ jùlọ nípa ohun tí wọ́n ń wí. Ìwọ kò sì níí jẹ wọ́n nípá (láti gbàgbọ́). Nítorí náà, fi al-Ƙur’ān ṣe ìrántí fún ẹni tí ó ń páyà ìlérí Mi.
Read Surah Qaf in another language
- English (word by word)
- Albanian
- Amazigh
- Amharic
- Assamese
- Azerbaijani
- Bambara
- Bangla
- Bosnian
- Bulgarian
- Chechen
- Chinese
- Czech
- Dari
- Dhivehi
- Dutch
- Finnish
- French
- German
- Gujarati
- Hausa
- Hebrew
- Hindi
- Indonesian
- Italian
- Japanese
- Kannada
- Kazakh
- Khmer
- Kinyarwanda
- Korean
- Kurdish
- Luganda
- Malay
- Malayalam
- Maranao
- Marathi
- Nepali
- Norwegian
- Oromo
- Pashto
- Persian
- Polish
- Portuguese
- Romanian
- Russian
- Sindhi
- Sinhala
- Somali
- Spanish
- Swahili
- Swedish
- Tagalog
- Tajik
- Tamil
- Tatar
- Telugu
- Thai
- Turkish
- Ukrainian
- Urdu
- Uyghur
- Uzbek
- Vietnamese
- Yao
All 114 surahs in Yoruba: the Qur’an in Yoruba.
Yoruba translation: Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni, from Quran.com. Transliteration: Quran.com. Recitation: Mishary Alafasy, from EveryAyah.com. MyDugsi is a learning aid, not a replacement for a qualified teacher.