Surah Ar-Ra'd in Yoruba: translation and audio
Surah 13 · الرعد · The Thunder · 43 verses
Surah Ar-Ra'd verse by verse: the Arabic with a recitation you can repeat, the transliteration, and the Yoruba translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni. For the meaning of every word, see Surah Ar-Ra'd word by word in English.
Verse 1
الٓمٓر ۚ تِلْكَ ءَايَـٰتُ ٱلْكِتَـٰبِ ۗ وَٱلَّذِىٓ أُنزِلَ إِلَيْكَ مِن رَّبِّكَ ٱلْحَقُّ وَلَـٰكِنَّ أَكْثَرَ ٱلنَّاسِ لَا يُؤْمِنُونَ
Transliteration alif-lam-meem-ra til'ka āyātu l-kitābi wa-alladhī unzila ilayka min rabbika l-ḥaqu walākinna akthara l-nāsi lā yu'minūna
Yoruba ’Alif lām mīm rọ̄. (Allāhu ló mọ ohun tí Ó gbàlérò pẹ̀lú àwọn háràfí náà.)Ìwọ̀nyí ni àwọn āyah Tírà náà. Àti pé òdodo ni ohun tí wọ́n sọ̀kalẹ̀ fún ọ láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ àwọn ènìyàn kò gbàgbọ́.
Verse 2
ٱللَّهُ ٱلَّذِى رَفَعَ ٱلسَّمَـٰوَٰتِ بِغَيْرِ عَمَدٍ تَرَوْنَهَا ۖ ثُمَّ ٱسْتَوَىٰ عَلَى ٱلْعَرْشِ ۖ وَسَخَّرَ ٱلشَّمْسَ وَٱلْقَمَرَ ۖ كُلٌّ يَجْرِى لِأَجَلٍ مُّسَمًّى ۚ يُدَبِّرُ ٱلْأَمْرَ يُفَصِّلُ ٱلْـَٔايَـٰتِ لَعَلَّكُم بِلِقَآءِ رَبِّكُمْ تُوقِنُونَ
Transliteration al-lahu alladhī rafaʿa l-samāwāti bighayri ʿamadin tarawnahā thumma is'tawā ʿalā l-ʿarshi wasakhara l-shamsa wal-qamara kullun yajrī li-ajalin musamman yudabbiru l-amra yufaṣṣilu l-āyāti laʿallakum biliqāi rabbikum tūqinūna
Yoruba Allāhu ni Ẹni tí Ó gbé àwọn sánmọ̀ ga sókè láì sí àwọn òpó kan (fún un) tí ẹ lè fojú rí. Lẹ́yìn náà, Ó gúnwà sórí Ìtẹ́-ọlá. Ó rọ òòrùn àti òṣùpá; ìkọ̀ọ̀kan wọn máa rìn fún gbèdéke àkókò kan.Ó ń ṣe ètò ọ̀rọ̀ (ẹ̀dá). Ó ń ṣe àlàyé àwọn āyah nítorí kí ẹ lè mọ àmọ̀dájú nípa ìpàdé Olúwa yín.
Verse 3
وَهُوَ ٱلَّذِى مَدَّ ٱلْأَرْضَ وَجَعَلَ فِيهَا رَوَٰسِىَ وَأَنْهَـٰرًا ۖ وَمِن كُلِّ ٱلثَّمَرَٰتِ جَعَلَ فِيهَا زَوْجَيْنِ ٱثْنَيْنِ ۖ يُغْشِى ٱلَّيْلَ ٱلنَّهَارَ ۚ إِنَّ فِى ذَٰلِكَ لَـَٔايَـٰتٍ لِّقَوْمٍ يَتَفَكَّرُونَ
Transliteration wahuwa alladhī madda l-arḍa wajaʿala fīhā rawāsiya wa-anhāran wamin kulli l-thamarāti jaʿala fīhā zawjayni ith'nayni yugh'shī al-layla l-nahāra inna fī dhālika laāyātin liqawmin yatafakkarūna
Yoruba Òun ni Ẹni tí Ó tẹ́ ilẹ̀ pẹrẹsẹ. Ó sì fi àwọn àpáta tó dúró gbagidi àti àwọn odò tó ń ṣàn sínú ilẹ̀. Àti pé nínú gbogbo àwọn èso, Ó ṣe é ní oríṣi méjì-méjì.Ó ń fi òru bo ọ̀sán lójú. Dájúdájú àwọn àmì wà nínú ìyẹn fún ìjọ tó ní àròjinlẹ̀.
Verse 4
وَفِى ٱلْأَرْضِ قِطَعٌ مُّتَجَـٰوِرَٰتٌ وَجَنَّـٰتٌ مِّنْ أَعْنَـٰبٍ وَزَرْعٌ وَنَخِيلٌ صِنْوَانٌ وَغَيْرُ صِنْوَانٍ يُسْقَىٰ بِمَآءٍ وَٰحِدٍ وَنُفَضِّلُ بَعْضَهَا عَلَىٰ بَعْضٍ فِى ٱلْأُكُلِ ۚ إِنَّ فِى ذَٰلِكَ لَـَٔايَـٰتٍ لِّقَوْمٍ يَعْقِلُونَ
Transliteration wafī l-arḍi qiṭaʿun mutajāwirātun wajannātun min aʿnābin wazarʿun wanakhīlun ṣin'wānun waghayru ṣin'wānin yus'qā bimāin wāḥidin wanufaḍḍilu baʿḍahā ʿalā baʿḍin fī l-ukuli inna fī dhālika laāyātin liqawmin yaʿqilūna
Yoruba Ó tún wà nínú ilẹ̀ àwọn abala-abala ilẹ̀ (oníran-ànran) tó wà nítòsí ara wọnàti àwọn ọgbà oko àjàrà, irúgbìn àti igi dàbínù tó pẹka àti èyí tí kò pẹka, tí wọ́n ń fún wọn ní omi ẹyọ kan mu. (Síbẹ̀síbẹ̀) A ṣe àjùlọ fún apá kan rẹ̀ lórí apá kan níbi àwọn èso wọn. Dájúdájú àwọn àmì wà nínú ìyẹn fún ìjọ tó ní làákàyè.
Verse 5
۞ وَإِن تَعْجَبْ فَعَجَبٌ قَوْلُهُمْ أَءِذَا كُنَّا تُرَٰبًا أَءِنَّا لَفِى خَلْقٍ جَدِيدٍ ۗ أُو۟لَـٰٓئِكَ ٱلَّذِينَ كَفَرُوا۟ بِرَبِّهِمْ ۖ وَأُو۟لَـٰٓئِكَ ٱلْأَغْلَـٰلُ فِىٓ أَعْنَاقِهِمْ ۖ وَأُو۟لَـٰٓئِكَ أَصْحَـٰبُ ٱلنَّارِ ۖ هُمْ فِيهَا خَـٰلِدُونَ
Transliteration wa-in taʿjab faʿajabun qawluhum a-idhā kunnā turāban a-innā lafī khalqin jadīdin ulāika alladhīna kafarū birabbihim wa-ulāika l-aghlālu fī aʿnāqihim wa-ulāika aṣḥābu l-nāri hum fīhā khālidūna
Yoruba Tí o bá ṣèèmọ̀, èèmọ̀ mà ni ọ̀rọ̀ (ẹnu) wọn (nípa bí wọ́n ṣe sọ pé): “Ṣé nígbà tí a bá ti di erùpẹ̀ tán, ṣé nígbà náà ni àwa yóò tún di ẹ̀dá titun?” Àwọn wọ̀nyẹn ni àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ nínú Olúwa wọn. Àwọn wọ̀nyẹn ni ẹ̀wọ̀n ń bẹ lọ́rùn wọn. Àwọn wọ̀nyẹn sì ni èrò inú Iná. Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀.
Verse 6
وَيَسْتَعْجِلُونَكَ بِٱلسَّيِّئَةِ قَبْلَ ٱلْحَسَنَةِ وَقَدْ خَلَتْ مِن قَبْلِهِمُ ٱلْمَثُلَـٰتُ ۗ وَإِنَّ رَبَّكَ لَذُو مَغْفِرَةٍ لِّلنَّاسِ عَلَىٰ ظُلْمِهِمْ ۖ وَإِنَّ رَبَّكَ لَشَدِيدُ ٱلْعِقَابِ
Transliteration wayastaʿjilūnaka bil-sayi-ati qabla l-ḥasanati waqad khalat min qablihimu l-mathulātu wa-inna rabbaka ladhū maghfiratin lilnnāsi ʿalā ẓul'mihim wa-inna rabbaka lashadīdu l-ʿiqābi
Yoruba Wọ́n tún ń kán ọ lójú pé kí aburú ṣẹlẹ̀ ṣíwájú rere. Àwọn ìyà (tó jẹ irú wọn) kúkú ti ṣẹlẹ̀ ṣíwájú wọn. Àti pé dájúdájú Olúwa rẹ ni Aláforíjìn fún àwọn ènìyàn lórí àbòsí (ọwọ́) wọn. Dájúdájú Olúwa rẹ le níbi ìyà.
Verse 7
وَيَقُولُ ٱلَّذِينَ كَفَرُوا۟ لَوْلَآ أُنزِلَ عَلَيْهِ ءَايَةٌ مِّن رَّبِّهِۦٓ ۗ إِنَّمَآ أَنتَ مُنذِرٌ ۖ وَلِكُلِّ قَوْمٍ هَادٍ
Transliteration wayaqūlu alladhīna kafarū lawlā unzila ʿalayhi āyatun min rabbihi innamā anta mundhirun walikulli qawmin hādin
Yoruba Àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ ń wí pé: “Kí ni kò jẹ́ kí wọ́n sọ àmì kan kalẹ̀ fún un láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ̀?” Olùkìlọ̀ mà ni ìwọ. Olùtọ́sọ́nà sì wà fún ìjọ kọ̀ọ̀kan.1
Verse 8
ٱللَّهُ يَعْلَمُ مَا تَحْمِلُ كُلُّ أُنثَىٰ وَمَا تَغِيضُ ٱلْأَرْحَامُ وَمَا تَزْدَادُ ۖ وَكُلُّ شَىْءٍ عِندَهُۥ بِمِقْدَارٍ
Transliteration al-lahu yaʿlamu mā taḥmilu kullu unthā wamā taghīḍu l-arḥāmu wamā tazdādu wakullu shayin ʿindahu bimiq'dārin
Yoruba Allāhu mọ ohun tí obìnrin kọ̀ọ̀kan ní lóyún àti ohun tí ilé ọmọ yóò fi dín kù (nínú ọjọ́ ìbímọ) àti ohun tí ó máa fi lékún. N̄ǹkan kọ̀ọ̀kan ló sì ní òdíwọ̀n lọ́dọ̀ Rẹ̀.
Verse 9
عَـٰلِمُ ٱلْغَيْبِ وَٱلشَّهَـٰدَةِ ٱلْكَبِيرُ ٱلْمُتَعَالِ
Transliteration ʿālimu l-ghaybi wal-shahādati l-kabīru l-mutaʿāli
Yoruba (Allāhu ni) Onímọ̀-ìkọ̀kọ̀-àti- gban̄gba. Ó tóbi, Ó ga jùlọ.
Verse 10
سَوَآءٌ مِّنكُم مَّنْ أَسَرَّ ٱلْقَوْلَ وَمَن جَهَرَ بِهِۦ وَمَنْ هُوَ مُسْتَخْفٍۭ بِٱلَّيْلِ وَسَارِبٌۢ بِٱلنَّهَارِ
Transliteration sawāon minkum man asarra l-qawla waman jahara bihi waman huwa mus'takhfin bi-al-layli wasāribun bil-nahāri
Yoruba Bákan náà ni (lọ́dọ̀ Allāhu), ẹni tí ó fi ọ̀rọ̀ pamọ́ sínú nínú yín àti ẹni tí ó sọ ọ́ síta pẹ̀lú ẹni tí ó fi òru bojú àti ẹni tí ó ń rìn kiri ní ọ̀sán.
Verse 11
لَهُۥ مُعَقِّبَـٰتٌ مِّنۢ بَيْنِ يَدَيْهِ وَمِنْ خَلْفِهِۦ يَحْفَظُونَهُۥ مِنْ أَمْرِ ٱللَّهِ ۗ إِنَّ ٱللَّهَ لَا يُغَيِّرُ مَا بِقَوْمٍ حَتَّىٰ يُغَيِّرُوا۟ مَا بِأَنفُسِهِمْ ۗ وَإِذَآ أَرَادَ ٱللَّهُ بِقَوْمٍ سُوٓءًا فَلَا مَرَدَّ لَهُۥ ۚ وَمَا لَهُم مِّن دُونِهِۦ مِن وَالٍ
Transliteration lahu muʿaqqibātun min bayni yadayhi wamin khalfihi yaḥfaẓūnahu min amri l-lahi inna l-laha lā yughayyiru mā biqawmin ḥattā yughayyirū mā bi-anfusihim wa-idhā arāda l-lahu biqawmin sūan falā maradda lahu wamā lahum min dūnihi min wālin
Yoruba Ó ń bẹ fún ènìyàn (kọ̀ọ̀kan) àwọn mọlāika tí ń gbaṣẹ́ fúnra wọn; wọ́n wà níwájú (ènìyàn) àti lẹ́yìn rẹ̀; wọ́n ń ṣọ́ (iṣẹ́ ọwọ́) rẹ̀ pẹ̀lú àṣẹ Allāhu. Dájúdájú Allāhu kò níí ṣe ìyípadà n̄ǹkan tó ń bẹ lọ́dọ̀ ìjọ kan títí wọn yóò fi yí n̄ǹkan tó ń bẹ nínú ẹ̀mí wọn padà. Nígbà tí Allāhu bá gbèrò aburú kan ro ìjọ kan, kò sí ẹni tó lè dá a padà. Kò sì sí aláààbò kan fún wọn lẹ́yìn Rẹ̀.
Verse 12
هُوَ ٱلَّذِى يُرِيكُمُ ٱلْبَرْقَ خَوْفًا وَطَمَعًا وَيُنشِئُ ٱلسَّحَابَ ٱلثِّقَالَ
Transliteration huwa alladhī yurīkumu l-barqa khawfan waṭamaʿan wayunshi-u l-saḥāba l-thiqāla
Yoruba Òun ni Ẹni tó ń fi mọ̀nàmọ́ná hàn yín ní ìbẹ̀rù àti ní ìrètí (fún yín). Ó sì ń ṣẹ̀dá ẹ̀ṣújò tó ṣú dẹ̀dẹ̀.
Verse 13
وَيُسَبِّحُ ٱلرَّعْدُ بِحَمْدِهِۦ وَٱلْمَلَـٰٓئِكَةُ مِنْ خِيفَتِهِۦ وَيُرْسِلُ ٱلصَّوَٰعِقَ فَيُصِيبُ بِهَا مَن يَشَآءُ وَهُمْ يُجَـٰدِلُونَ فِى ٱللَّهِ وَهُوَ شَدِيدُ ٱلْمِحَالِ
Transliteration wayusabbiḥu l-raʿdu biḥamdihi wal-malāikatu min khīfatihi wayur'silu l-ṣawāʿiqa fayuṣību bihā man yashāu wahum yujādilūna fī l-lahi wahuwa shadīdu l-miḥāli
Yoruba Àrá ń ṣe àfọ̀mọ́ pẹ̀lú ẹyìn fún Un, àwọn mọlāika náà (ń ṣe bẹ́ẹ̀) fún ìbẹ̀rù Rẹ̀. Ó ń rán iná láti ojú sánmọ̀ níṣẹ́. Ó sì ń fi kọlu ẹni tí Ó bá fẹ́. Síbẹ̀ wọ́n ń jiyàn nípa Allāhu. (Allāhu) sì lágbára gan-an.
Verse 14
لَهُۥ دَعْوَةُ ٱلْحَقِّ ۖ وَٱلَّذِينَ يَدْعُونَ مِن دُونِهِۦ لَا يَسْتَجِيبُونَ لَهُم بِشَىْءٍ إِلَّا كَبَـٰسِطِ كَفَّيْهِ إِلَى ٱلْمَآءِ لِيَبْلُغَ فَاهُ وَمَا هُوَ بِبَـٰلِغِهِۦ ۚ وَمَا دُعَآءُ ٱلْكَـٰفِرِينَ إِلَّا فِى ضَلَـٰلٍ
Transliteration lahu daʿwatu l-ḥaqi wa-alladhīna yadʿūna min dūnihi lā yastajībūna lahum bishayin illā kabāsiṭi kaffayhi ilā l-māi liyablugha fāhu wamā huwa bibālighihi wamā duʿāu l-kāfirīna illā fī ḍalālin
Yoruba TiRẹ̀ ni ìpè òdodo. Àwọn tí wọ́n ń pè lẹ́yìn Rẹ̀, wọn kò lè fi kiní kan jẹ́ pè wọn àfi bí ẹni tí ó tẹ́wọ́ rẹ̀ méjèèjì (lásán) sí omi nítorí kí omi lè dé ẹnu rẹ̀. Omi kò sì lè dé ẹnu rẹ̀. Àdúà (àti ìpè) àwọn aláìgbàgbọ́ kò sì jẹ́ kiní kan bí kò ṣe sínú ìṣìnà.1
Verse 15
وَلِلَّهِ يَسْجُدُ مَن فِى ٱلسَّمَـٰوَٰتِ وَٱلْأَرْضِ طَوْعًا وَكَرْهًا وَظِلَـٰلُهُم بِٱلْغُدُوِّ وَٱلْـَٔاصَالِ ۩
Transliteration walillahi yasjudu man fī l-samāwāti wal-arḍi ṭawʿan wakarhan waẓilāluhum bil-ghuduwi wal-āṣāli
Yoruba Allāhu ni àwọn tó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ ń forí kanlẹ̀ fún, wọ́n fẹ́, wọ́n kọ̀, - òòji wọn (náà ń ṣe bẹ́ẹ̀) - ní òwúrọ̀ àti ní ìrọ̀lẹ́.1
Verse 16
قُلْ مَن رَّبُّ ٱلسَّمَـٰوَٰتِ وَٱلْأَرْضِ قُلِ ٱللَّهُ ۚ قُلْ أَفَٱتَّخَذْتُم مِّن دُونِهِۦٓ أَوْلِيَآءَ لَا يَمْلِكُونَ لِأَنفُسِهِمْ نَفْعًا وَلَا ضَرًّا ۚ قُلْ هَلْ يَسْتَوِى ٱلْأَعْمَىٰ وَٱلْبَصِيرُ أَمْ هَلْ تَسْتَوِى ٱلظُّلُمَـٰتُ وَٱلنُّورُ ۗ أَمْ جَعَلُوا۟ لِلَّهِ شُرَكَآءَ خَلَقُوا۟ كَخَلْقِهِۦ فَتَشَـٰبَهَ ٱلْخَلْقُ عَلَيْهِمْ ۚ قُلِ ٱللَّهُ خَـٰلِقُ كُلِّ شَىْءٍ وَهُوَ ٱلْوَٰحِدُ ٱلْقَهَّـٰرُ
Transliteration qul man rabbu l-samāwāti wal-arḍi quli l-lahu qul afa-ittakhadhtum min dūnihi awliyāa lā yamlikūna li-anfusihim nafʿan walā ḍarran qul hal yastawī l-aʿmā wal-baṣīru am hal tastawī l-ẓulumātu wal-nūru am jaʿalū lillahi shurakāa khalaqū kakhalqihi fatashābaha l-khalqu ʿalayhim quli l-lahu khāliqu kulli shayin wahuwa l-wāḥidu l-qahāru
Yoruba Sọ pé: “Ta ni Olúwa àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀?” Sọ pé: “Allāhu ni.” Sọ pé: “Ṣé lẹ́yìn Rẹ̀ ni ẹ tún mú àwọn aláfẹ̀yìntì kan, tí wọn kò ní ìkápá oore àti ìnira fún ẹ̀mí ara wọn?” Sọ pé: “Ṣé afọ́jú àti olùríran dọ́gba bí? Tàbí àwọn òkùnkùn àti ìmọ́lẹ̀ dọ́gba? Tàbí wọ́n yóò fún Allāhu ní àwọn akẹgbẹ́ kan tí àwọn náà dá ẹ̀dá bíi ti ẹ̀dá Rẹ̀, (tó bẹ́ẹ̀ gẹ́) tí ẹ̀dá fi jọra wọn lójú wọn?” Sọ pé: “Allāhu ni Ẹlẹ́dàá gbogbo n̄ǹkan. Òun sì ni Ọ̀kan ṣoṣo, Olùborí.
Verse 17
أَنزَلَ مِنَ ٱلسَّمَآءِ مَآءً فَسَالَتْ أَوْدِيَةٌۢ بِقَدَرِهَا فَٱحْتَمَلَ ٱلسَّيْلُ زَبَدًا رَّابِيًا ۚ وَمِمَّا يُوقِدُونَ عَلَيْهِ فِى ٱلنَّارِ ٱبْتِغَآءَ حِلْيَةٍ أَوْ مَتَـٰعٍ زَبَدٌ مِّثْلُهُۥ ۚ كَذَٰلِكَ يَضْرِبُ ٱللَّهُ ٱلْحَقَّ وَٱلْبَـٰطِلَ ۚ فَأَمَّا ٱلزَّبَدُ فَيَذْهَبُ جُفَآءً ۖ وَأَمَّا مَا يَنفَعُ ٱلنَّاسَ فَيَمْكُثُ فِى ٱلْأَرْضِ ۚ كَذَٰلِكَ يَضْرِبُ ٱللَّهُ ٱلْأَمْثَالَ
Transliteration anzala mina l-samāi māan fasālat awdiyatun biqadarihā fa-iḥ'tamala l-saylu zabadan rābiyan wamimmā yūqidūna ʿalayhi fī l-nāri ib'tighāa ḥil'yatin aw matāʿin zabadun mith'luhu kadhālika yaḍribu l-lahu l-ḥaqa wal-bāṭila fa-ammā l-zabadu fayadhhabu jufāan wa-ammā mā yanfaʿu l-nāsa fayamkuthu fī l-arḍi kadhālika yaḍribu l-lahu l-amthāla
Yoruba Ó ń sọ omi kalẹ̀ láti sánmọ̀. Àwọn ojú-odò sì ń ṣàn pẹ̀lú òdiwọ̀n rẹ̀. Àgbàrá sì ń gbé ìfòfó orí-omi tó ga lọ. Bákan náà, nínú n̄ǹkan tí wọ́n ń yọ́ nínú iná láti fi ṣe n̄ǹkan-ọ̀ṣọ́ tàbí n̄ǹkan-èlò, òhun náà ní ìfòfó bí irú rẹ̀. Báyẹn ni Allāhu ṣe ń mú àkàwé wá fún òdodo àti irọ́. Ní ti ìfòfó, ó máa lọ ní ìlọ pàǹtí. Ní ti èyí tí ó sì máa ṣe àwọn ènìyàn ní àǹfààní, ó máa dúró sí orí ilẹ̀. Báyẹn ni Allāhu ṣe ń mú àwọn àkàwé wá.1
Verse 18
لِلَّذِينَ ٱسْتَجَابُوا۟ لِرَبِّهِمُ ٱلْحُسْنَىٰ ۚ وَٱلَّذِينَ لَمْ يَسْتَجِيبُوا۟ لَهُۥ لَوْ أَنَّ لَهُم مَّا فِى ٱلْأَرْضِ جَمِيعًا وَمِثْلَهُۥ مَعَهُۥ لَٱفْتَدَوْا۟ بِهِۦٓ ۚ أُو۟لَـٰٓئِكَ لَهُمْ سُوٓءُ ٱلْحِسَابِ وَمَأْوَىٰهُمْ جَهَنَّمُ ۖ وَبِئْسَ ٱلْمِهَادُ
Transliteration lilladhīna is'tajābū lirabbihimu l-ḥus'nā wa-alladhīna lam yastajībū lahu law anna lahum mā fī l-arḍi jamīʿan wamith'lahu maʿahu la-if'tadaw bihi ulāika lahum sūu l-ḥisābi wamawāhum jahannamu wabi'sa l-mihādu
Yoruba Ohun rere (ìyẹn Ọgbà Ìdẹ̀ra) wà fún àwọn tó jẹ́pè Olúwa wọn. Àwọn tí kò sì jẹ́pè Rẹ̀, tí ó bá jẹ́ pé tiwọn ni gbogbo n̄ǹkan tó ń bẹ lórí ilẹ̀ pátápátá àti irú rẹ̀ pẹ̀lú rẹ̀, wọn ìbá fi ṣèràpadà (fún ẹ̀mí ara wọn níbi Iná). Àwọn wọ̀nyẹn ni aburú ìṣírò-iṣẹ́ wà fún.Iná Jahanamọ ni ibùgbé wọn; ibùgbé náà sì burú.
Verse 19
۞ أَفَمَن يَعْلَمُ أَنَّمَآ أُنزِلَ إِلَيْكَ مِن رَّبِّكَ ٱلْحَقُّ كَمَنْ هُوَ أَعْمَىٰٓ ۚ إِنَّمَا يَتَذَكَّرُ أُو۟لُوا۟ ٱلْأَلْبَـٰبِ
Transliteration afaman yaʿlamu annamā unzila ilayka min rabbika l-ḥaqu kaman huwa aʿmā innamā yatadhakkaru ulū l-albābi
Yoruba Ǹjẹ́ ẹni tí ó mọ̀ pé òdodo kúkú ni n̄ǹkan tí wọ́n sọ̀kalẹ̀ fún ọ láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ, ó wa dà bí ẹni tí ó fọ́jú (nípa rẹ̀ bí)? Àwọn onílàákàyè ló ń lo ìrántí.
Verse 20
ٱلَّذِينَ يُوفُونَ بِعَهْدِ ٱللَّهِ وَلَا يَنقُضُونَ ٱلْمِيثَـٰقَ
Transliteration alladhīna yūfūna biʿahdi l-lahi walā yanquḍūna l-mīthāqa
Yoruba (Àwọn ni) àwọn tó ń mú àdéhùn Allāhu ṣẹ. Àti pé wọn kì í tú àdéhùn.
Verse 21
وَٱلَّذِينَ يَصِلُونَ مَآ أَمَرَ ٱللَّهُ بِهِۦٓ أَن يُوصَلَ وَيَخْشَوْنَ رَبَّهُمْ وَيَخَافُونَ سُوٓءَ ٱلْحِسَابِ
Transliteration wa-alladhīna yaṣilūna mā amara l-lahu bihi an yūṣala wayakhshawna rabbahum wayakhāfūna sūa l-ḥisābi
Yoruba (Àwọn ni) àwọn tó ń da ohun tí Allāhu pa láṣẹ pé kí wọ́n dàpọ̀ pọ̀. Wọ́n ń páyà Olúwa wọn. Wọ́n sì ń páyà aburú ìṣírò-iṣẹ́.
Verse 22
وَٱلَّذِينَ صَبَرُوا۟ ٱبْتِغَآءَ وَجْهِ رَبِّهِمْ وَأَقَامُوا۟ ٱلصَّلَوٰةَ وَأَنفَقُوا۟ مِمَّا رَزَقْنَـٰهُمْ سِرًّا وَعَلَانِيَةً وَيَدْرَءُونَ بِٱلْحَسَنَةِ ٱلسَّيِّئَةَ أُو۟لَـٰٓئِكَ لَهُمْ عُقْبَى ٱلدَّارِ
Transliteration wa-alladhīna ṣabarū ib'tighāa wajhi rabbihim wa-aqāmū l-ṣalata wa-anfaqū mimmā razaqnāhum sirran waʿalāniyatan wayadraūna bil-ḥasanati l-sayi-ata ulāika lahum ʿuq'bā l-dāri
Yoruba (Àwọn ni) àwọn tó ṣe sùúrù láti fi wá Ojú rere Olúwa wọn. Wọ́n ń kírun. Wọ́n ń ná nínú ohun tí A pèsè fún wọn ní ìkọ̀kọ̀ àti ní gban̄gba. Wọ́n sì ń fi rere dènà aburú.Àwọn wọ̀nyẹn ni àtubọ̀tán Ilé rere ń bẹ fún.
Verse 23
جَنَّـٰتُ عَدْنٍ يَدْخُلُونَهَا وَمَن صَلَحَ مِنْ ءَابَآئِهِمْ وَأَزْوَٰجِهِمْ وَذُرِّيَّـٰتِهِمْ ۖ وَٱلْمَلَـٰٓئِكَةُ يَدْخُلُونَ عَلَيْهِم مِّن كُلِّ بَابٍ
Transliteration jannātu ʿadnin yadkhulūnahā waman ṣalaḥa min ābāihim wa-azwājihim wadhurriyyātihim wal-malāikatu yadkhulūna ʿalayhim min kulli bābin
Yoruba Inú àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra gbére ni wọ́n máa wọ̀, (àwọn) àti ẹni tó bá ṣe rere nínú àwọn bàbá wọn, àwọn ìyàwó wọn àti àwọn àrọ́mọdọ́mọ wọn. Àwọn mọlāika yó sì máa wọlé tọ̀ wọ́n láti ẹnu ọ̀nà kọ̀ọ̀kan.
Verse 24
سَلَـٰمٌ عَلَيْكُم بِمَا صَبَرْتُمْ ۚ فَنِعْمَ عُقْبَى ٱلدَّارِ
Transliteration salāmun ʿalaykum bimā ṣabartum faniʿ'ma ʿuq'bā l-dāri
Yoruba (Wọn yóò sọ pé): “Àlàáfíà fún yín nítorí sùúrù yín.” Àtubọ̀tán Ilé rere náà sì dára.
Verse 25
وَٱلَّذِينَ يَنقُضُونَ عَهْدَ ٱللَّهِ مِنۢ بَعْدِ مِيثَـٰقِهِۦ وَيَقْطَعُونَ مَآ أَمَرَ ٱللَّهُ بِهِۦٓ أَن يُوصَلَ وَيُفْسِدُونَ فِى ٱلْأَرْضِ ۙ أُو۟لَـٰٓئِكَ لَهُمُ ٱللَّعْنَةُ وَلَهُمْ سُوٓءُ ٱلدَّارِ
Transliteration wa-alladhīna yanquḍūna ʿahda l-lahi min baʿdi mīthāqihi wayaqṭaʿūna mā amara l-lahu bihi an yūṣala wayuf'sidūna fī l-arḍi ulāika lahumu l-laʿnatu walahum sūu l-dāri
Yoruba Àwọn tó ń tú àdéhùn Allāhu lẹ́yìn tí wọ́n ti gba àdéhùn Rẹ̀, tí wọ́n ń já ohun tí Allāhu pa láṣẹ pé kí wọ́n dàpọ̀, tí wọ́n sì ń ṣe ìbàjẹ́ lórí ilẹ̀; àwọn wọ̀nyẹn ni ègún wà fún. Àti pé Ilé (Iná) burúkú wà fún wọn.
Verse 26
ٱللَّهُ يَبْسُطُ ٱلرِّزْقَ لِمَن يَشَآءُ وَيَقْدِرُ ۚ وَفَرِحُوا۟ بِٱلْحَيَوٰةِ ٱلدُّنْيَا وَمَا ٱلْحَيَوٰةُ ٱلدُّنْيَا فِى ٱلْـَٔاخِرَةِ إِلَّا مَتَـٰعٌ
Transliteration al-lahu yabsuṭu l-riz'qa liman yashāu wayaqdiru wafariḥū bil-ḥayati l-dun'yā wamā l-ḥayatu l-dun'yā fī l-ākhirati illā matāʿun
Yoruba Allāhu ń tẹ́ arísìkí sílẹ̀ rẹgẹdẹ fún ẹni tí Ó bá fẹ́. Ó sì ń díwọ̀n rẹ̀ (fún ẹni tí Ó bá fẹ́). Wọ́n sì dunnú sí ìṣẹ̀mí ilé ayé! Kí sì ni ìṣẹ̀mí ayé ní ẹ̀gbẹ́ ti ọ̀run bí kò ṣe ìgbádùn bín-íntín.
Verse 27
وَيَقُولُ ٱلَّذِينَ كَفَرُوا۟ لَوْلَآ أُنزِلَ عَلَيْهِ ءَايَةٌ مِّن رَّبِّهِۦ ۗ قُلْ إِنَّ ٱللَّهَ يُضِلُّ مَن يَشَآءُ وَيَهْدِىٓ إِلَيْهِ مَنْ أَنَابَ
Transliteration wayaqūlu alladhīna kafarū lawlā unzila ʿalayhi āyatun min rabbihi qul inna l-laha yuḍillu man yashāu wayahdī ilayhi man anāba
Yoruba Àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ ń wí pé: “Kí ni kò jẹ́ kí wọ́n sọ àmì kan kalẹ̀ fún un láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ̀?” Sọ pé: “Dájúdájú Allāhu ń ṣi ẹni tí Ó bá fẹ́ lọ́nà. Ó sì ń fi ọ̀nà mọ ẹni tí ó bá ṣẹ́rí padà sọ́dọ̀ Rẹ̀.”
Verse 28
ٱلَّذِينَ ءَامَنُوا۟ وَتَطْمَئِنُّ قُلُوبُهُم بِذِكْرِ ٱللَّهِ ۗ أَلَا بِذِكْرِ ٱللَّهِ تَطْمَئِنُّ ٱلْقُلُوبُ
Transliteration alladhīna āmanū wataṭma-innu qulūbuhum bidhik'ri l-lahi alā bidhik'ri l-lahi taṭma-innu l-qulūbu
Yoruba Àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo, tí ọkàn wọn sì balẹ̀ pẹ̀lú ìrántí Allāhu; ẹ gbọ́, pẹ̀lú ìrántí Allāhu ni àwọn ọkàn máa fi balẹ̀.1
Verse 29
ٱلَّذِينَ ءَامَنُوا۟ وَعَمِلُوا۟ ٱلصَّـٰلِحَـٰتِ طُوبَىٰ لَهُمْ وَحُسْنُ مَـَٔابٍ
Transliteration alladhīna āmanū waʿamilū l-ṣāliḥāti ṭūbā lahum waḥus'nu maābin
Yoruba Àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe àwọn iṣẹ́ rere, orí ire àti àbọ̀ rere wà fún wọn.
Verse 30
كَذَٰلِكَ أَرْسَلْنَـٰكَ فِىٓ أُمَّةٍ قَدْ خَلَتْ مِن قَبْلِهَآ أُمَمٌ لِّتَتْلُوَا۟ عَلَيْهِمُ ٱلَّذِىٓ أَوْحَيْنَآ إِلَيْكَ وَهُمْ يَكْفُرُونَ بِٱلرَّحْمَـٰنِ ۚ قُلْ هُوَ رَبِّى لَآ إِلَـٰهَ إِلَّا هُوَ عَلَيْهِ تَوَكَّلْتُ وَإِلَيْهِ مَتَابِ
Transliteration kadhālika arsalnāka fī ummatin qad khalat min qablihā umamun litatluwā ʿalayhimu alladhī awḥaynā ilayka wahum yakfurūna bil-raḥmāni qul huwa rabbī lā ilāha illā huwa ʿalayhi tawakkaltu wa-ilayhi matābi
Yoruba Báyẹn ni A ṣe rán ọ níṣẹ́ sí ìjọ kan, - àwọn ìjọ kan kúkú ti ré kọjá lọ ṣíwájú wọn -, nítorí kí o lè máa ka n̄ǹkan tí A fi ránṣẹ́ sí ọ ní ìmísí fún wọn. Síbẹ̀síbẹ̀ wọ́n ń ṣàì gbàgbọ́ nínú Àjọkẹ́-ayé. Sọ pé: “Òun ni Olúwa mi. Kò sí ọlọ́hun kan tí a gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo àyàfi Òun. Òun ni mo gbáralé. Ọ̀dọ̀ Rẹ̀ sì ni àbọ̀ mi.”
Verse 31
وَلَوْ أَنَّ قُرْءَانًا سُيِّرَتْ بِهِ ٱلْجِبَالُ أَوْ قُطِّعَتْ بِهِ ٱلْأَرْضُ أَوْ كُلِّمَ بِهِ ٱلْمَوْتَىٰ ۗ بَل لِّلَّهِ ٱلْأَمْرُ جَمِيعًا ۗ أَفَلَمْ يَا۟يْـَٔسِ ٱلَّذِينَ ءَامَنُوٓا۟ أَن لَّوْ يَشَآءُ ٱللَّهُ لَهَدَى ٱلنَّاسَ جَمِيعًا ۗ وَلَا يَزَالُ ٱلَّذِينَ كَفَرُوا۟ تُصِيبُهُم بِمَا صَنَعُوا۟ قَارِعَةٌ أَوْ تَحُلُّ قَرِيبًا مِّن دَارِهِمْ حَتَّىٰ يَأْتِىَ وَعْدُ ٱللَّهِ ۚ إِنَّ ٱللَّهَ لَا يُخْلِفُ ٱلْمِيعَادَ
Transliteration walaw anna qur'ānan suyyirat bihi l-jibālu aw quṭṭiʿat bihi l-arḍu aw kullima bihi l-mawtā bal lillahi l-amru jamīʿan afalam yāy'asi alladhīna āmanū an law yashāu l-lahu lahadā l-nāsa jamīʿan walā yazālu alladhīna kafarū tuṣībuhum bimā ṣanaʿū qāriʿatun aw taḥullu qarīban min dārihim ḥattā yatiya waʿdu l-lahi inna l-laha lā yukh'lifu l-mīʿāda
Yoruba Tí ó bá jẹ́ pé dájúdájú al-Ƙur’ān, wọ́n ké e láti fi mú àwọn àpáta rìn (kúrò ní àyè wọn), tàbí wọ́n fi gé ilẹ̀ (kélekèle, kí ó yanu fún àwọn àlùmọ́nì), tàbí wọ́n fi bá àwọn òkú sọ̀rọ̀ (kí wọ́n sì jí dìde, wọn kò níí gbàgbọ́). Àmọ́ sá, ti Allāhu ni gbogbo àṣẹ pátápátá. Ṣé àwọn tó gbàgbọ́ kò mọ̀ pé tí ó bá jẹ́ pé Allāhu bá fẹ́, ìbá tọ́ gbogbo ènìyàn sọ́nà. Àjálù kò sì níí yé ṣẹlẹ̀ sí àwọn aláìgbàgbọ́ nítorí ohun tí wọ́n ṣe níṣẹ́ tàbí (àjálù náà kò níí yé) sọ̀kalẹ̀ sí tòsí ilé wọn títí di ìgbà tí àdéhùn Allāhu yóò fi dé. Dájúdájú Allāhu kò níí yapa àdéhùn.
Verse 32
وَلَقَدِ ٱسْتُهْزِئَ بِرُسُلٍ مِّن قَبْلِكَ فَأَمْلَيْتُ لِلَّذِينَ كَفَرُوا۟ ثُمَّ أَخَذْتُهُمْ ۖ فَكَيْفَ كَانَ عِقَابِ
Transliteration walaqadi us'tuh'zi-a birusulin min qablika fa-amlaytu lilladhīna kafarū thumma akhadhtuhum fakayfa kāna ʿiqābi
Yoruba Dájúdájú wọn ti fi àwọn Òjíṣẹ́ kan ṣe yẹ̀yẹ́ ṣíwájú rẹ. Mo sì lọ́ àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ lára. Lẹ́yìn náà, Mo gbá wọn mú. Nítorí náà, báwo ni ìyà (tí mo fi jẹ wọ́n) ti rí (lára wọn ná)!
Verse 33
أَفَمَنْ هُوَ قَآئِمٌ عَلَىٰ كُلِّ نَفْسٍۭ بِمَا كَسَبَتْ ۗ وَجَعَلُوا۟ لِلَّهِ شُرَكَآءَ قُلْ سَمُّوهُمْ ۚ أَمْ تُنَبِّـُٔونَهُۥ بِمَا لَا يَعْلَمُ فِى ٱلْأَرْضِ أَم بِظَـٰهِرٍ مِّنَ ٱلْقَوْلِ ۗ بَلْ زُيِّنَ لِلَّذِينَ كَفَرُوا۟ مَكْرُهُمْ وَصُدُّوا۟ عَنِ ٱلسَّبِيلِ ۗ وَمَن يُضْلِلِ ٱللَّهُ فَمَا لَهُۥ مِنْ هَادٍ
Transliteration afaman huwa qāimun ʿalā kulli nafsin bimā kasabat wajaʿalū lillahi shurakāa qul sammūhum am tunabbiūnahu bimā lā yaʿlamu fī l-arḍi am biẓāhirin mina l-qawli bal zuyyina lilladhīna kafarū makruhum waṣuddū ʿani l-sabīli waman yuḍ'lili l-lahu famā lahu min hādin
Yoruba Ǹjẹ́ Ẹni tí Ó ń mójútó ẹ̀mí kọ̀ọ̀kan nípa iṣẹ́ tí ó ṣe (dà bí ẹni tí kò lè ṣe bẹ́ẹ̀ bí? Síbẹ̀) wọ́n tún bá Allāhu wá àwọn akẹgbẹ́ kan! Sọ pé: “Ẹ dárúkọ wọn ná.” Tàbí ẹ̀yin yóò fún (Allāhu) ní ìró ohun tí kò mọ̀ lórí ilẹ̀ tàbí (ẹ fẹ́ mú) irọ́ àti àbá dídá wá? Rárá, wọ́n ti ṣe ète àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ ní ọ̀ṣọ́ fún wọn ni. Wọ́n sì ṣẹ́rí wọn kúrò lójú ọ̀nà òdodo. Ẹnikẹ́ni tí Allāhu bá ṣì lọ́nà, kò níí sí olùtọ́sọ́nà kan fún un.
Verse 34
لَّهُمْ عَذَابٌ فِى ٱلْحَيَوٰةِ ٱلدُّنْيَا ۖ وَلَعَذَابُ ٱلْـَٔاخِرَةِ أَشَقُّ ۖ وَمَا لَهُم مِّنَ ٱللَّهِ مِن وَاقٍ
Transliteration lahum ʿadhābun fī l-ḥayati l-dun'yā walaʿadhābu l-ākhirati ashaqqu wamā lahum mina l-lahi min wāqin
Yoruba Ìyà wà fún wọn nínú ìṣẹ̀mí ayé (yìí). Ìyà ti Ọjọ́ Ìkẹ́yìn kúkú gbópọn jùlọ. Kò sì níí sì aláàbò kan fún wọn lọ́dọ̀ Allāhu.
Verse 35
۞ مَّثَلُ ٱلْجَنَّةِ ٱلَّتِى وُعِدَ ٱلْمُتَّقُونَ ۖ تَجْرِى مِن تَحْتِهَا ٱلْأَنْهَـٰرُ ۖ أُكُلُهَا دَآئِمٌ وَظِلُّهَا ۚ تِلْكَ عُقْبَى ٱلَّذِينَ ٱتَّقَوا۟ ۖ وَّعُقْبَى ٱلْكَـٰفِرِينَ ٱلنَّارُ
Transliteration mathalu l-janati allatī wuʿida l-mutaqūna tajrī min taḥtihā l-anhāru ukuluhā dāimun waẓilluhā til'ka ʿuq'bā alladhīna ittaqaw waʿuq'bā l-kāfirīna l-nāru
Yoruba Àpèjúwe Ọgbà Ìdẹ̀ra tí wọ́n ṣe ní àdéhùn fún àwọn olùbẹ̀rù Allāhu (ni èyí tí) àwọn odò ń ṣàn kọjá nísàlẹ̀ rẹ̀. Èso rẹ̀ àti ibòji rẹ̀ yó máa wà títí láéláé. Ìyẹn ni ìkángun àwọn tó bẹ̀rù (Allāhu). Iná sì ni ìkángun àwọn aláìgbàgbọ́.
Verse 36
وَٱلَّذِينَ ءَاتَيْنَـٰهُمُ ٱلْكِتَـٰبَ يَفْرَحُونَ بِمَآ أُنزِلَ إِلَيْكَ ۖ وَمِنَ ٱلْأَحْزَابِ مَن يُنكِرُ بَعْضَهُۥ ۚ قُلْ إِنَّمَآ أُمِرْتُ أَنْ أَعْبُدَ ٱللَّهَ وَلَآ أُشْرِكَ بِهِۦٓ ۚ إِلَيْهِ أَدْعُوا۟ وَإِلَيْهِ مَـَٔابِ
Transliteration wa-alladhīna ātaynāhumu l-kitāba yafraḥūna bimā unzila ilayka wamina l-aḥzābi man yunkiru baʿḍahu qul innamā umir'tu an aʿbuda l-laha walā ush'rika bihi ilayhi adʿū wa-ilayhi maābi
Yoruba Àwọn tí A fún ní Tírà ń dunnú sí ohun tí A sọ̀kalẹ̀ fún ọ. Ó sì wà nínú àwọn ìjọ kèfèrí-parapọ̀ tó ń ṣe àtakò sí apá kan rẹ̀. Sọ pé: “N̄ǹkan tí wọ́n pa mí láṣẹ rẹ̀ ni pé kí n̄g jọ́sìn fún Allāhu. Èmi kò sì gbọdọ̀ wá akẹgbẹ́ fún Un. Ọ̀dọ̀ Rẹ̀ ni mò ń pèpè sí. Ọ̀dọ̀ Rẹ̀ sì ni àbọ̀ mi.”
Verse 37
وَكَذَٰلِكَ أَنزَلْنَـٰهُ حُكْمًا عَرَبِيًّا ۚ وَلَئِنِ ٱتَّبَعْتَ أَهْوَآءَهُم بَعْدَ مَا جَآءَكَ مِنَ ٱلْعِلْمِ مَا لَكَ مِنَ ٱللَّهِ مِن وَلِىٍّ وَلَا وَاقٍ
Transliteration wakadhālika anzalnāhu ḥuk'man ʿarabiyyan wala-ini ittabaʿta ahwāahum baʿdamā jāaka mina l-ʿil'mi mā laka mina l-lahi min waliyyin walā wāqin
Yoruba Báyẹn ni A ṣe sọ̀ ọ́ kalẹ̀ ní ìdájọ́ pẹ̀lú èdè Lárúbáwá. Dájúdájú tí o bá fi lè tẹ̀lé ìfẹ́-inú wọn, lẹ́yìn n̄ǹkan tí ó dé bá ọ nínú ìmọ̀, kò sí aláàbò àti olùṣọ́ kan fún ọ mọ́ lọ́dọ̀ Allāhu.
Verse 38
وَلَقَدْ أَرْسَلْنَا رُسُلًا مِّن قَبْلِكَ وَجَعَلْنَا لَهُمْ أَزْوَٰجًا وَذُرِّيَّةً ۚ وَمَا كَانَ لِرَسُولٍ أَن يَأْتِىَ بِـَٔايَةٍ إِلَّا بِإِذْنِ ٱللَّهِ ۗ لِكُلِّ أَجَلٍ كِتَابٌ
Transliteration walaqad arsalnā rusulan min qablika wajaʿalnā lahum azwājan wadhurriyyatan wamā kāna lirasūlin an yatiya biāyatin illā bi-idh'ni l-lahi likulli ajalin kitābun
Yoruba Dájúdájú A ti rán àwọn Òjíṣẹ́ kan níṣẹ́ ṣíwájú rẹ. A sì fún wọn ní àwọn ìyàwó àti àwọn ọmọọmọ.Kò lẹ́tọ̀ọ́ fún Òjíṣẹ́ kan láti mú àmì kan wá àyàfi pẹ̀lú ìyọ̀ǹda Allāhu.2 Gbogbo ìṣẹ̀lẹ̀ ló ní àkọsílẹ̀.
Verse 39
يَمْحُوا۟ ٱللَّهُ مَا يَشَآءُ وَيُثْبِتُ ۖ وَعِندَهُۥٓ أُمُّ ٱلْكِتَـٰبِ
Transliteration yamḥū l-lahu mā yashāu wayuth'bitu waʿindahu ummu l-kitābi
Yoruba Allāhu ń pa ohun tí Ó bá fẹ́ rẹ́. Ó sì ń mú (ohun tí Ó bá fẹ́) ṣẹ. Ọ̀dọ̀ Rẹ̀ sì ni Tírà Ìpìlẹ̀ wà.1
Verse 40
وَإِن مَّا نُرِيَنَّكَ بَعْضَ ٱلَّذِى نَعِدُهُمْ أَوْ نَتَوَفَّيَنَّكَ فَإِنَّمَا عَلَيْكَ ٱلْبَلَـٰغُ وَعَلَيْنَا ٱلْحِسَابُ
Transliteration wa-in mā nuriyannaka baʿḍa alladhī naʿiduhum aw natawaffayannaka fa-innamā ʿalayka l-balāghu waʿalaynā l-ḥisābu
Yoruba Ó ṣeé ṣe kí Á fi apá kan èyí tí A ṣe ní ìlérí fún wọn hàn ọ́ tàbí kí Á ti gba ẹ̀mí rẹ (ṣíwájú àsìkò náà), ìkéde (ẹ̀sìn) nìkan ni ojúṣe tìrẹ, ìṣírò-iṣẹ́ sì ni tiWa.
Verse 41
أَوَلَمْ يَرَوْا۟ أَنَّا نَأْتِى ٱلْأَرْضَ نَنقُصُهَا مِنْ أَطْرَافِهَا ۚ وَٱللَّهُ يَحْكُمُ لَا مُعَقِّبَ لِحُكْمِهِۦ ۚ وَهُوَ سَرِيعُ ٱلْحِسَابِ
Transliteration awalam yaraw annā natī l-arḍa nanquṣuhā min aṭrāfihā wal-lahu yaḥkumu lā muʿaqqiba liḥuk'mihi wahuwa sarīʿu l-ḥisābi
Yoruba Ṣé wọn kò wòye pé dájúdájú À ń dé sórí ilẹ̀, À ń dín in kù (mọ́ àwọn aláìgbàgbọ́ lọ́wọ́) láti àwọn eteetí ìlú (wọ inú ìlú nípa fífún àwọn mùsùlùmí ní ìṣẹ́gun lórí wọn)? Allāhu l’Ó ń ṣe ìdájọ́. Kò sí ẹnì kan tí ó lè dá ìdájọ́ Rẹ̀ padà (fún Un). Òun sì ni Olùyára níbi ìṣírò-iṣẹ́.
Verse 42
وَقَدْ مَكَرَ ٱلَّذِينَ مِن قَبْلِهِمْ فَلِلَّهِ ٱلْمَكْرُ جَمِيعًا ۖ يَعْلَمُ مَا تَكْسِبُ كُلُّ نَفْسٍ ۗ وَسَيَعْلَمُ ٱلْكُفَّـٰرُ لِمَنْ عُقْبَى ٱلدَّارِ
Transliteration waqad makara alladhīna min qablihim falillahi l-makru jamīʿan yaʿlamu mā taksibu kullu nafsin wasayaʿlamu l-kufāru liman ʿuq'bā l-dāri
Yoruba Dájúdájú àwọn tó ṣíwájú wọn déte. Ti Allāhu sì ni gbogbo ète pátápátá.Ó mọ ohun tí ẹ̀mí kọ̀ọ̀kan ń ṣe níṣẹ́. Àti pé àwọn aláìgbàgbọ́ ń bọ̀ wá mọ ẹni tí àtubọ̀tán Ilé (rere) wà fún.
Verse 43
وَيَقُولُ ٱلَّذِينَ كَفَرُوا۟ لَسْتَ مُرْسَلًا ۚ قُلْ كَفَىٰ بِٱللَّهِ شَهِيدًۢا بَيْنِى وَبَيْنَكُمْ وَمَنْ عِندَهُۥ عِلْمُ ٱلْكِتَـٰبِ
Transliteration wayaqūlu alladhīna kafarū lasta mur'salan qul kafā bil-lahi shahīdan baynī wabaynakum waman ʿindahu ʿil'mu l-kitābi
Yoruba Àwọn aláìgbàgbọ́ ń wí pé: “Ìwọ kì í ṣe Òjíṣẹ́.” Sọ pé: “Allāhu tó ní Ẹlẹ́rìí láààrin èmi àti ẹ̀yin àti ẹni tí ìmọ̀ Tírà ń bẹ lọ́dọ̀ rẹ̀.
Read Surah Ar-Ra'd in another language
- English (word by word)
- Albanian
- Amazigh
- Amharic
- Assamese
- Azerbaijani
- Bambara
- Bangla
- Bosnian
- Bulgarian
- Chechen
- Chinese
- Czech
- Dari
- Dhivehi
- Dutch
- Finnish
- French
- German
- Gujarati
- Hausa
- Hebrew
- Hindi
- Indonesian
- Italian
- Japanese
- Kannada
- Kazakh
- Khmer
- Kinyarwanda
- Korean
- Kurdish
- Luganda
- Malay
- Malayalam
- Maranao
- Marathi
- Nepali
- Norwegian
- Oromo
- Pashto
- Persian
- Polish
- Portuguese
- Romanian
- Russian
- Sindhi
- Sinhala
- Somali
- Spanish
- Swahili
- Swedish
- Tagalog
- Tajik
- Tamil
- Tatar
- Telugu
- Thai
- Turkish
- Ukrainian
- Urdu
- Uyghur
- Uzbek
- Vietnamese
- Yao
All 114 surahs in Yoruba: the Qur’an in Yoruba.
Yoruba translation: Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni, from Quran.com. Transliteration: Quran.com. Recitation: Mishary Alafasy, from EveryAyah.com. MyDugsi is a learning aid, not a replacement for a qualified teacher.