MyDugsiStart learning

Surah Ali 'Imran in Yoruba: translation and audio

Surah 3 · آل عمران · Family of Imran · 200 verses

Surah Ali 'Imran verse by verse: the Arabic with a recitation you can repeat, the transliteration, and the Yoruba translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni. For the meaning of every word, see Surah Ali 'Imran word by word in English.

Verse 1

الٓمٓ

Transliteration alif-lam-meem

Yoruba ’Alif lām mīm. (Allāhu ló mọ ohun tí Ó gbàlérò pẹ̀lú àwọn háràfí náà.)1

Verse 2

ٱللَّهُ لَآ إِلَـٰهَ إِلَّا هُوَ ٱلْحَىُّ ٱلْقَيُّومُ

Transliteration al-lahu lā ilāha illā huwa l-ḥayu l-qayūmu

Yoruba Allāhu, kò sí ọlọ́hun kan tí a gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo àyàfi Òun, Alààyè, Alámòjúútó-ẹ̀dá.

Verse 3

نَزَّلَ عَلَيْكَ ٱلْكِتَـٰبَ بِٱلْحَقِّ مُصَدِّقًا لِّمَا بَيْنَ يَدَيْهِ وَأَنزَلَ ٱلتَّوْرَىٰةَ وَٱلْإِنجِيلَ

Transliteration nazzala ʿalayka l-kitāba bil-ḥaqi muṣaddiqan limā bayna yadayhi wa-anzala l-tawrāta wal-injīla

Yoruba Ó sọ Tírà (al-Ƙur’ān) kalẹ̀ fún ọ pẹ̀lú òdodo, ó ń fi ohun tó jẹ́ òdodo rinlẹ̀ nípa èyí tó wà ṣíwájú rẹ̀. Ó sì sọ at-Taorāh àti al-’Injīl kalẹ̀.

Verse 4

مِن قَبْلُ هُدًى لِّلنَّاسِ وَأَنزَلَ ٱلْفُرْقَانَ ۗ إِنَّ ٱلَّذِينَ كَفَرُوا۟ بِـَٔايَـٰتِ ٱللَّهِ لَهُمْ عَذَابٌ شَدِيدٌ ۗ وَٱللَّهُ عَزِيزٌ ذُو ٱنتِقَامٍ

Transliteration min qablu hudan lilnnāsi wa-anzala l-fur'qāna inna alladhīna kafarū biāyāti l-lahi lahum ʿadhābun shadīdun wal-lahu ʿazīzun dhū intiqāmin

Yoruba Tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀ wọ́n jẹ́ ìmọ̀nà fún àwọn ènìyàn.Ó tún sọ ọ̀rọ̀-ìpínyà (ọ̀rọ̀ tó ń ṣèpínyà láààrin òdodo àti irọ́) kalẹ̀.2 Dájúdájú àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ nínú àwọn āyah Allāhu, ìyà tó le ń bẹ fún wọn. Allāhu sì ni Alágbára, Olùgbẹ̀san.

Verse 5

إِنَّ ٱللَّهَ لَا يَخْفَىٰ عَلَيْهِ شَىْءٌ فِى ٱلْأَرْضِ وَلَا فِى ٱلسَّمَآءِ

Transliteration inna l-laha lā yakhfā ʿalayhi shayon fī l-arḍi walā fī l-samāi

Yoruba Dájúdájú Allāhu, kò sí kiní kan tó pamọ́ fún Un nínú ilẹ̀ àti nínú sánmọ̀.

Verse 6

هُوَ ٱلَّذِى يُصَوِّرُكُمْ فِى ٱلْأَرْحَامِ كَيْفَ يَشَآءُ ۚ لَآ إِلَـٰهَ إِلَّا هُوَ ٱلْعَزِيزُ ٱلْحَكِيمُ

Transliteration huwa alladhī yuṣawwirukum fī l-arḥāmi kayfa yashāu lā ilāha illā huwa l-ʿazīzu l-ḥakīmu

Yoruba Òun ni Ẹni tí Ó ń yàwòrán yín sínú àpòlùkẹ́ bí Ó ṣe fẹ́. Kò sí ọlọ́hun kan tí a gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo àyàfi Òun, Alágbára Ọlọ́gbọ́n.

Verse 7

هُوَ ٱلَّذِىٓ أَنزَلَ عَلَيْكَ ٱلْكِتَـٰبَ مِنْهُ ءَايَـٰتٌ مُّحْكَمَـٰتٌ هُنَّ أُمُّ ٱلْكِتَـٰبِ وَأُخَرُ مُتَشَـٰبِهَـٰتٌ ۖ فَأَمَّا ٱلَّذِينَ فِى قُلُوبِهِمْ زَيْغٌ فَيَتَّبِعُونَ مَا تَشَـٰبَهَ مِنْهُ ٱبْتِغَآءَ ٱلْفِتْنَةِ وَٱبْتِغَآءَ تَأْوِيلِهِۦ ۗ وَمَا يَعْلَمُ تَأْوِيلَهُۥٓ إِلَّا ٱللَّهُ ۗ وَٱلرَّٰسِخُونَ فِى ٱلْعِلْمِ يَقُولُونَ ءَامَنَّا بِهِۦ كُلٌّ مِّنْ عِندِ رَبِّنَا ۗ وَمَا يَذَّكَّرُ إِلَّآ أُو۟لُوا۟ ٱلْأَلْبَـٰبِ

Transliteration huwa alladhī anzala ʿalayka l-kitāba min'hu āyātun muḥ'kamātun hunna ummu l-kitābi wa-ukharu mutashābihātun fa-ammā alladhīna fī qulūbihim zayghun fayattabiʿūna mā tashābaha min'hu ib'tighāa l-fit'nati wa-ib'tighāa tawīlihi wamā yaʿlamu tawīlahu illā l-lahu wal-rāsikhūna fī l-ʿil'mi yaqūlūna āmannā bihi kullun min ʿindi rabbinā wamā yadhakkaru illā ulū l-albābi

Yoruba Òun ni Ẹni tí Ó sọ Tírà kalẹ̀ fún ọ; àwọn āyah aláìnípọ́n-na wà nínú rẹ̀ - àwọn sì ni ìpìlẹ̀ Tírà-, onípọ́n-na sì ni ìyókù.2 Ní ti àwọn tí ìgbúnrí kúrò níbi òdodo wà nínú ọkàn wọn, wọn yóò máa tẹ̀lé èyí tó ní pọ́n-na nínú rẹ̀ láti fi wá wàhálà àti láti fí wá ìtúmọ̀ (òdì) fún un. Kò sì sí ẹni tó nímọ̀ pàápàá ìtúmọ̀ rẹ̀ àfi Allāhu. Àwọn àgbà nínú ìmọ̀ ẹ̀sìn, wọ́n ń sọ pé: “A gbà á gbọ́. Láti ọ̀dọ̀ Olúwa wa ni gbogbo rẹ̀ (ti sọ̀kalẹ̀).” Kò sí ẹni tó ń lo ìrántí àyàfi àwọn onílàákàyè.

Verse 8

رَبَّنَا لَا تُزِغْ قُلُوبَنَا بَعْدَ إِذْ هَدَيْتَنَا وَهَبْ لَنَا مِن لَّدُنكَ رَحْمَةً ۚ إِنَّكَ أَنتَ ٱلْوَهَّابُ

Transliteration rabbanā lā tuzigh qulūbanā baʿda idh hadaytanā wahab lanā min ladunka raḥmatan innaka anta l-wahābu

Yoruba Olúwa wa, má ṣe yí wa lọ́kàn padà lẹ́yìn tí O ti tọ́ wa sọ́nà. Ta wá lọ́rẹ ìkẹ́ láti ọ̀dọ̀ Rẹ, dájúdájú Ìwọ gan-an ni Ọlọ́rẹ.

Verse 9

رَبَّنَآ إِنَّكَ جَامِعُ ٱلنَّاسِ لِيَوْمٍ لَّا رَيْبَ فِيهِ ۚ إِنَّ ٱللَّهَ لَا يُخْلِفُ ٱلْمِيعَادَ

Transliteration rabbanā innaka jāmiʿu l-nāsi liyawmin lā rayba fīhi inna l-laha lā yukh'lifu l-mīʿāda

Yoruba Olúwa wa, dájúdájú Ìwọ l’O máa kó àwọn ènìyàn jọ ní ọjọ́ kan, tí kò sí iyèméjì nínú rẹ̀. Dájúdájú Allāhu kì í yẹ àdéhùn.

Verse 10

إِنَّ ٱلَّذِينَ كَفَرُوا۟ لَن تُغْنِىَ عَنْهُمْ أَمْوَٰلُهُمْ وَلَآ أَوْلَـٰدُهُم مِّنَ ٱللَّهِ شَيْـًٔا ۖ وَأُو۟لَـٰٓئِكَ هُمْ وَقُودُ ٱلنَّارِ

Transliteration inna alladhīna kafarū lan tugh'niya ʿanhum amwāluhum walā awlāduhum mina l-lahi shayan wa-ulāika hum waqūdu l-nāri

Yoruba Dájúdájú àwọn tó ṣàì gbàgbọ́, àwọn dúkìá wọn àti àwọn ọmọ wọn kò níí rọ̀ wọ́n lọ́rọ̀ kiní kan lọ́dọ̀ Allāhu. Àwọn wọ̀nyẹn, àwọn ni n̄ǹkan ìkoná.

Verse 11

كَدَأْبِ ءَالِ فِرْعَوْنَ وَٱلَّذِينَ مِن قَبْلِهِمْ ۚ كَذَّبُوا۟ بِـَٔايَـٰتِنَا فَأَخَذَهُمُ ٱللَّهُ بِذُنُوبِهِمْ ۗ وَٱللَّهُ شَدِيدُ ٱلْعِقَابِ

Transliteration kadabi āli fir'ʿawna wa-alladhīna min qablihim kadhabū biāyātinā fa-akhadhahumu l-lahu bidhunūbihim wal-lahu shadīdu l-ʿiqābi

Yoruba (Ìṣesí wọn) dà bí ìṣesí àwọn ènìyàn Fir‘aon àti àwọn tó ṣíwájú wọn, tí wọ́n pe àwọn āyah Wa ní irọ́. Nítorí náà, Allāhu mú wọn nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Allāhu sì le níbi ìyà.

Verse 12

قُل لِّلَّذِينَ كَفَرُوا۟ سَتُغْلَبُونَ وَتُحْشَرُونَ إِلَىٰ جَهَنَّمَ ۚ وَبِئْسَ ٱلْمِهَادُ

Transliteration qul lilladhīna kafarū satugh'labūna watuḥ'sharūna ilā jahannama wabi'sa l-mihādu

Yoruba Sọ fún àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ pé: “Wọ́n máa ṣẹ́gun yín. Wọ́n sì máa ko yín jọ lọ sí iná Jahanamọ. Ibùgbé náà sì burú.”

Verse 13

قَدْ كَانَ لَكُمْ ءَايَةٌ فِى فِئَتَيْنِ ٱلْتَقَتَا ۖ فِئَةٌ تُقَـٰتِلُ فِى سَبِيلِ ٱللَّهِ وَأُخْرَىٰ كَافِرَةٌ يَرَوْنَهُم مِّثْلَيْهِمْ رَأْىَ ٱلْعَيْنِ ۚ وَٱللَّهُ يُؤَيِّدُ بِنَصْرِهِۦ مَن يَشَآءُ ۗ إِنَّ فِى ذَٰلِكَ لَعِبْرَةً لِّأُو۟لِى ٱلْأَبْصَـٰرِ

Transliteration qad kāna lakum āyatun fī fi-atayni l-taqatā fi-atun tuqātilu fī sabīli l-lahi wa-ukh'rā kāfiratun yarawnahum mith'layhim raya l-ʿayni wal-lahu yu-ayyidu binaṣrihi man yashāu inna fī dhālika laʿib'ratan li-ulī l-abṣāri

Yoruba Àmì kúkú wà fún yín níbi àwọn ìjọ méjì tí wọ́n pàdé (ara wọn). Ìjọ kan ń jà fún ààbò ẹ̀sìn Allāhu. Aláìgbàgbọ́ sì ni ìjọ kejì tí ó ń rí ìjọ kìíní bí ìlọ́po méjì wọn ní rírí ojú.Allāhu ń fi àrànṣe Rẹ̀ ṣe ìkúnlọ́wọ́ fún ẹni tí Ó bá fẹ́. Dájúdájú àríwòye wà nínú ìyẹn fún àwọn olùríran.

Verse 14

زُيِّنَ لِلنَّاسِ حُبُّ ٱلشَّهَوَٰتِ مِنَ ٱلنِّسَآءِ وَٱلْبَنِينَ وَٱلْقَنَـٰطِيرِ ٱلْمُقَنطَرَةِ مِنَ ٱلذَّهَبِ وَٱلْفِضَّةِ وَٱلْخَيْلِ ٱلْمُسَوَّمَةِ وَٱلْأَنْعَـٰمِ وَٱلْحَرْثِ ۗ ذَٰلِكَ مَتَـٰعُ ٱلْحَيَوٰةِ ٱلدُّنْيَا ۖ وَٱللَّهُ عِندَهُۥ حُسْنُ ٱلْمَـَٔابِ

Transliteration zuyyina lilnnāsi ḥubbu l-shahawāti mina l-nisāi wal-banīna wal-qanāṭīri l-muqanṭarati mina l-dhahabi wal-fiḍati wal-khayli l-musawamati wal-anʿāmi wal-ḥarthi dhālika matāʿu l-ḥayati l-dun'yā wal-lahu ʿindahu ḥus'nu l-maābi

Yoruba Wọ́n ṣe é ní ọ̀ṣọ́ fún àwọn ènìyàn; ìfẹ́ ìgbádùn ara lára àwọn obìnrin, àwọn ọmọkùnrin, àwọn owó wúrà àti fàdákà púpọ̀ jaburata àti àwọn ẹṣin tí wọ́n ṣe ní ọ̀ṣọ́, àwọn ẹran-ọ̀sìn àti (n̄ǹkan) oko. Ìyẹn ni n̄ǹkan ìgbáyé-gbádùn. Ọ̀dọ̀ Allāhu sì ni àbọ̀ rere wà.

Verse 15

۞ قُلْ أَؤُنَبِّئُكُم بِخَيْرٍ مِّن ذَٰلِكُمْ ۚ لِلَّذِينَ ٱتَّقَوْا۟ عِندَ رَبِّهِمْ جَنَّـٰتٌ تَجْرِى مِن تَحْتِهَا ٱلْأَنْهَـٰرُ خَـٰلِدِينَ فِيهَا وَأَزْوَٰجٌ مُّطَهَّرَةٌ وَرِضْوَٰنٌ مِّنَ ٱللَّهِ ۗ وَٱللَّهُ بَصِيرٌۢ بِٱلْعِبَادِ

Transliteration qul a-unabbi-ukum bikhayrin min dhālikum lilladhīna ittaqaw ʿinda rabbihim jannātun tajrī min taḥtihā l-anhāru khālidīna fīhā wa-azwājun muṭahharatun wariḍ'wānun mina l-lahi wal-lahu baṣīrun bil-ʿibādi

Yoruba Sọ pé: “Ṣé kí n̄g sọ n̄ǹkan tó dára ju ìyẹn lọ fún yín?” Àwọn Ọgbà tí àwọn odò ń ṣàn ní ìsàlẹ̀ rẹ̀ ń bẹ fún àwọn tó bá bẹ̀rù (Allāhu) ní ọ̀dọ̀ Olúwa wọn. Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀. Àwọn ìyàwó mímọ́ àti ìyọ́nú láti ọ̀dọ̀ Allāhu (tún ń bẹ fún wọn). Allāhu sì ni Olùríran nípa àwọn ẹrúsìn,

Verse 16

ٱلَّذِينَ يَقُولُونَ رَبَّنَآ إِنَّنَآ ءَامَنَّا فَٱغْفِرْ لَنَا ذُنُوبَنَا وَقِنَا عَذَابَ ٱلنَّارِ

Transliteration alladhīna yaqūlūna rabbanā innanā āmannā fa-igh'fir lanā dhunūbanā waqinā ʿadhāba l-nāri

Yoruba Àwọn tó ń sọ pé: “Olúwa wa, dájúdájú àwa gbàgbọ́. Nítorí náà, forí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa jìn wá. Kí O sì ṣọ́ wa níbi ìyà Iná.”

Verse 17

ٱلصَّـٰبِرِينَ وَٱلصَّـٰدِقِينَ وَٱلْقَـٰنِتِينَ وَٱلْمُنفِقِينَ وَٱلْمُسْتَغْفِرِينَ بِٱلْأَسْحَارِ

Transliteration al-ṣābirīna wal-ṣādiqīna wal-qānitīna wal-munfiqīna wal-mus'taghfirīna bil-asḥāri

Yoruba (Ọgbà Ìdẹ̀ra yẹn wà fún) àwọn onísùúrù, àwọn olódodo, àwọn olùtẹ̀lé-àṣẹ Allāhu, àwọn olùnáwó-fẹ́sìn àti àwọn olùtọrọ-àforíjìn ní àsìkò sààrì.

Verse 18

شَهِدَ ٱللَّهُ أَنَّهُۥ لَآ إِلَـٰهَ إِلَّا هُوَ وَٱلْمَلَـٰٓئِكَةُ وَأُو۟لُوا۟ ٱلْعِلْمِ قَآئِمًۢا بِٱلْقِسْطِ ۚ لَآ إِلَـٰهَ إِلَّا هُوَ ٱلْعَزِيزُ ٱلْحَكِيمُ

Transliteration shahida l-lahu annahu lā ilāha illā huwa wal-malāikatu wa-ulū l-ʿil'mi qāiman bil-qis'ṭi lā ilāha illā huwa l-ʿazīzu l-ḥakīmu

Yoruba Allāhu jẹ́rìí pé dájúdájú kò sí ọlọ́hun kan tí a gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo àyàfi Òun. Àwọn mọlāika àti onímọ̀ ẹ̀sìn (tún jẹ́rìí bẹ́ẹ̀.), Allāhu ni Onídéédé. Kò sí ọlọ́hun kan tí a gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo àyàfi Òun, Alágbára, Ọlọ́gbọ́n.

Verse 19

إِنَّ ٱلدِّينَ عِندَ ٱللَّهِ ٱلْإِسْلَـٰمُ ۗ وَمَا ٱخْتَلَفَ ٱلَّذِينَ أُوتُوا۟ ٱلْكِتَـٰبَ إِلَّا مِنۢ بَعْدِ مَا جَآءَهُمُ ٱلْعِلْمُ بَغْيًۢا بَيْنَهُمْ ۗ وَمَن يَكْفُرْ بِـَٔايَـٰتِ ٱللَّهِ فَإِنَّ ٱللَّهَ سَرِيعُ ٱلْحِسَابِ

Transliteration inna l-dīna ʿinda l-lahi l-is'lāmu wamā ikh'talafa alladhīna ūtū l-kitāba illā min baʿdi mā jāahumu l-ʿil'mu baghyan baynahum waman yakfur biāyāti l-lahi fa-inna l-laha sarīʿu l-ḥisābi

Yoruba Dájúdájú ẹ̀sìn tó wà lọ́dọ̀ Allāhu ni ’Islām. Àwọn tí A fún ní Tírà (àwọn yẹhudi àti nasọ̄rọ̄) kò yapa-ẹnu (lórí ẹ̀sìn náà) àfi lẹ́yìn tí ìmọ̀ dé bá wọn ní ti ìlara láààrin ara wọn (sí àwọn Ànábì - kí ọlà Allāhu máa bá wọn -). Ẹni tó bá ṣàì gbàgbọ́ nínú àwọn āyah Allāhu, dájúdájú Allāhu ni Olùyára níbi ìṣírò-iṣẹ́.

Verse 20

فَإِنْ حَآجُّوكَ فَقُلْ أَسْلَمْتُ وَجْهِىَ لِلَّهِ وَمَنِ ٱتَّبَعَنِ ۗ وَقُل لِّلَّذِينَ أُوتُوا۟ ٱلْكِتَـٰبَ وَٱلْأُمِّيِّـۧنَ ءَأَسْلَمْتُمْ ۚ فَإِنْ أَسْلَمُوا۟ فَقَدِ ٱهْتَدَوا۟ ۖ وَّإِن تَوَلَّوْا۟ فَإِنَّمَا عَلَيْكَ ٱلْبَلَـٰغُ ۗ وَٱللَّهُ بَصِيرٌۢ بِٱلْعِبَادِ

Transliteration fa-in ḥājjūka faqul aslamtu wajhiya lillahi wamani ittabaʿani waqul lilladhīna ūtū l-kitāba wal-umiyīna a-aslamtum fa-in aslamū faqadi ih'tadaw wa-in tawallaw fa-innamā ʿalayka l-balāghu wal-lahu baṣīrun bil-ʿibādi

Yoruba Tí wọ́n bá sì jà ọ́ níyàn, sọ pé: “Èmi àti ẹni tí ó tẹ̀lé mi juwọ́ jusẹ̀ sílẹ̀ (mùsùlùmí ni wá) fún Allāhu.” Kí o sì sọ fún àwọn tí A fún ní Tírà àti àwọn aláìmọ̀ọ́nkọmọ̀ọ́nkà (aláìnítírà) pé: “Ṣé ẹ máa gba ’Islām?” Tí wọ́n bá gba ’Islām, wọ́n ti mọ̀nà. Tí wọ́n bá sì kẹ̀yìn (sí’Islām), ìkéde (ẹ̀sìn) nìkan ni ojúṣe tìrẹ. Allāhu sì ni Olùríran nípa àwọn ẹrúsìn.

Verse 21

إِنَّ ٱلَّذِينَ يَكْفُرُونَ بِـَٔايَـٰتِ ٱللَّهِ وَيَقْتُلُونَ ٱلنَّبِيِّـۧنَ بِغَيْرِ حَقٍّ وَيَقْتُلُونَ ٱلَّذِينَ يَأْمُرُونَ بِٱلْقِسْطِ مِنَ ٱلنَّاسِ فَبَشِّرْهُم بِعَذَابٍ أَلِيمٍ

Transliteration inna alladhīna yakfurūna biāyāti l-lahi wayaqtulūna l-nabiyīna bighayri ḥaqqin wayaqtulūna alladhīna yamurūna bil-qis'ṭi mina l-nāsi fabashir'hum biʿadhābin alīmin

Yoruba Dájúdájú àwọn tó ń ṣàì gbàgbọ́ nínú àwọn āyah Allāhu, wọ́n tún ń pa àwọn Ànábì láì lẹ́tọ̀ọ́, wọ́n tún ń pa àwọn ènìyàn tí ń pàṣẹ ṣíṣe déédé àti ẹ̀tọ́, fún wọn ní ìró ìyà ẹlẹ́ta-eléro.

Verse 22

أُو۟لَـٰٓئِكَ ٱلَّذِينَ حَبِطَتْ أَعْمَـٰلُهُمْ فِى ٱلدُّنْيَا وَٱلْـَٔاخِرَةِ وَمَا لَهُم مِّن نَّـٰصِرِينَ

Transliteration ulāika alladhīna ḥabiṭat aʿmāluhum fī l-dun'yā wal-ākhirati wamā lahum min nāṣirīna

Yoruba Àwọn wọ̀nyẹn ni àwọn tí iṣẹ́ wọn ti bàjẹ́ ní ilé ayé àti ní ọ̀run. Wọn kò sì níí rí àwọn olùrànlọ́wọ́.

Verse 23

أَلَمْ تَرَ إِلَى ٱلَّذِينَ أُوتُوا۟ نَصِيبًا مِّنَ ٱلْكِتَـٰبِ يُدْعَوْنَ إِلَىٰ كِتَـٰبِ ٱللَّهِ لِيَحْكُمَ بَيْنَهُمْ ثُمَّ يَتَوَلَّىٰ فَرِيقٌ مِّنْهُمْ وَهُم مُّعْرِضُونَ

Transliteration alam tara ilā alladhīna ūtū naṣīban mina l-kitābi yud'ʿawna ilā kitābi l-lahi liyaḥkuma baynahum thumma yatawallā farīqun min'hum wahum muʿ'riḍūna

Yoruba Ṣé ìwọ kò wòye sí àwọn tí A fún ní ìpín kan nínú Tírà, tí À ń pè síbi Tírà Allāhu, nítorí kí ó lè ṣe ìdájọ́ láààrin wọn, lẹ́yìn náà tí ìjọ kan nínú wọn ń pẹ̀yìn dà, tí wọ́n sì ń gbúnrí?

Verse 24

ذَٰلِكَ بِأَنَّهُمْ قَالُوا۟ لَن تَمَسَّنَا ٱلنَّارُ إِلَّآ أَيَّامًا مَّعْدُودَٰتٍ ۖ وَغَرَّهُمْ فِى دِينِهِم مَّا كَانُوا۟ يَفْتَرُونَ

Transliteration dhālika bi-annahum qālū lan tamassanā l-nāru illā ayyāman maʿdūdātin wagharrahum fī dīnihim mā kānū yaftarūna

Yoruba Ìyẹn nítorí pé dájúdájú wọ́n wí pé: “Iná kò lè jó wa tayọ àwọn ọjọ́ tó lóǹkà.” Ohun tí wọ́n ń dá ní àdápa irọ́ sì tàn wọ́n jẹ nínú ẹ̀sìn wọn.

Verse 25

فَكَيْفَ إِذَا جَمَعْنَـٰهُمْ لِيَوْمٍ لَّا رَيْبَ فِيهِ وَوُفِّيَتْ كُلُّ نَفْسٍ مَّا كَسَبَتْ وَهُمْ لَا يُظْلَمُونَ

Transliteration fakayfa idhā jamaʿnāhum liyawmin lā rayba fīhi wawuffiyat kullu nafsin mā kasabat wahum lā yuẓ'lamūna

Yoruba Nítorí náà, báwo ni (ó ṣe máa rí fún wọn) nígbà tí A bá kó wọn jọ ní ọjọ́ kan, tí kò sí iyèméjì nínú rẹ̀? Àti pé A máa san ẹ̀mí kọ̀ọ̀kan ní ẹ̀san ohun tí ó ṣe níṣẹ́ ní ẹ̀kún-rẹ́rẹ́. Wọn kò sì níí ṣàbòsí sí wọn.

Verse 26

قُلِ ٱللَّهُمَّ مَـٰلِكَ ٱلْمُلْكِ تُؤْتِى ٱلْمُلْكَ مَن تَشَآءُ وَتَنزِعُ ٱلْمُلْكَ مِمَّن تَشَآءُ وَتُعِزُّ مَن تَشَآءُ وَتُذِلُّ مَن تَشَآءُ ۖ بِيَدِكَ ٱلْخَيْرُ ۖ إِنَّكَ عَلَىٰ كُلِّ شَىْءٍ قَدِيرٌ

Transliteration quli l-lahuma mālika l-mul'ki tu'tī l-mul'ka man tashāu watanziʿu l-mul'ka mimman tashāu watuʿizzu man tashāu watudhillu man tashāu biyadika l-khayru innaka ʿalā kulli shayin qadīrun

Yoruba Sọ pé: “Allāhu, Olùkápá ìjọba, Ò ń fi ìjọba fún ẹni tí O bá fẹ́. Ò ń gba ìjọba lọ́wọ́ ẹni tí O bá fẹ́. Ò ń buyì kún ẹni tí O bá fẹ́. O sì ń tàbùkù ẹni tí O bá fẹ́. Ọwọ́ Rẹ ni oore wà. Dájúdájú Ìwọ ni Alágbárá lórí gbogbo n̄ǹkan.

Verse 27

تُولِجُ ٱلَّيْلَ فِى ٱلنَّهَارِ وَتُولِجُ ٱلنَّهَارَ فِى ٱلَّيْلِ ۖ وَتُخْرِجُ ٱلْحَىَّ مِنَ ٱلْمَيِّتِ وَتُخْرِجُ ٱلْمَيِّتَ مِنَ ٱلْحَىِّ ۖ وَتَرْزُقُ مَن تَشَآءُ بِغَيْرِ حِسَابٍ

Transliteration tūliju al-layla fī l-nahāri watūliju l-nahāra fī al-layli watukh'riju l-ḥaya mina l-mayiti watukh'riju l-mayita mina l-ḥayi watarzuqu man tashāu bighayri ḥisābin

Yoruba Ò ń mú òru wọnú ọ̀sán.Ò ń mú ọ̀sán wọnú òru.2 Ò ń mú alààyè jáde lára òkú. Ò ń mú òkú jáde lára alààyè. O sì ń pèsè ìjẹ-ìmu àti ìgbádùn fún ẹni tí Ó bá fẹ́ láì níí ní ìṣírò.”3

Verse 28

لَّا يَتَّخِذِ ٱلْمُؤْمِنُونَ ٱلْكَـٰفِرِينَ أَوْلِيَآءَ مِن دُونِ ٱلْمُؤْمِنِينَ ۖ وَمَن يَفْعَلْ ذَٰلِكَ فَلَيْسَ مِنَ ٱللَّهِ فِى شَىْءٍ إِلَّآ أَن تَتَّقُوا۟ مِنْهُمْ تُقَىٰةً ۗ وَيُحَذِّرُكُمُ ٱللَّهُ نَفْسَهُۥ ۗ وَإِلَى ٱللَّهِ ٱلْمَصِيرُ

Transliteration lā yattakhidhi l-mu'minūna l-kāfirīna awliyāa min dūni l-mu'minīna waman yafʿal dhālika falaysa mina l-lahi fī shayin illā an tattaqū min'hum tuqātan wayuḥadhirukumu l-lahu nafsahu wa-ilā l-lahi l-maṣīru

Yoruba Àwọn onígbàgbọ́ òdodo kò gbọ́dọ̀ sọ àwọn aláìgbàgbọ́ di ọ̀rẹ́ àyò (ọ̀rẹ́ finúhannú) lẹ́yìn àwọn onígbàgbọ́ òdodo (ẹgbẹ́ wọn). Ẹnikẹ́ni tí ó bá ń ṣe ìyẹn, kò sí kiní kan fún un mọ́ lọ́dọ̀ Allāhu.Àfi tí ẹ bá ń (fi ọ̀rẹ́ orí ahọ́n) wá ìṣọ́ra lọ́dọ̀ wọn) dáadáa (lórí ìgbàgbọ́ yín).2 Allāhu ń kìlọ̀ ara Rẹ̀ fún yín. Ọ̀dọ̀ Allāhu sì ni àbọ̀ ẹ̀dá.

Verse 29

قُلْ إِن تُخْفُوا۟ مَا فِى صُدُورِكُمْ أَوْ تُبْدُوهُ يَعْلَمْهُ ٱللَّهُ ۗ وَيَعْلَمُ مَا فِى ٱلسَّمَـٰوَٰتِ وَمَا فِى ٱلْأَرْضِ ۗ وَٱللَّهُ عَلَىٰ كُلِّ شَىْءٍ قَدِيرٌ

Transliteration qul in tukh'fū mā fī ṣudūrikum aw tub'dūhu yaʿlamhu l-lahu wayaʿlamu mā fī l-samāwāti wamā fī l-arḍi wal-lahu ʿalā kulli shayin qadīrun

Yoruba Sọ pé: “Tí ẹ bá fi ohun tí ń bẹ nínú ọkàn yín pamọ́ tàbí ẹ fi hàn, Allāhu mọ̀ ọ́n. Ó sì mọ ohunkóhun tó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ohunkóhun tó wà nínú ilẹ̀. Allāhu sì ni Alágbára lórí gbogbo n̄ǹkan.

Verse 30

يَوْمَ تَجِدُ كُلُّ نَفْسٍ مَّا عَمِلَتْ مِنْ خَيْرٍ مُّحْضَرًا وَمَا عَمِلَتْ مِن سُوٓءٍ تَوَدُّ لَوْ أَنَّ بَيْنَهَا وَبَيْنَهُۥٓ أَمَدًۢا بَعِيدًا ۗ وَيُحَذِّرُكُمُ ٱللَّهُ نَفْسَهُۥ ۗ وَٱللَّهُ رَءُوفٌۢ بِٱلْعِبَادِ

Transliteration yawma tajidu kullu nafsin mā ʿamilat min khayrin muḥ'ḍaran wamā ʿamilat min sūin tawaddu law anna baynahā wabaynahu amadan baʿīdan wayuḥadhirukumu l-lahu nafsahu wal-lahu raūfun bil-ʿibādi

Yoruba Ní ọjọ́ tí ẹ̀mí kọ̀ọ̀kan yóò rí ohun tí ó ṣe nínú iṣẹ́ rere níwájú (rẹ̀) àti ohun tí ó ṣe nínú iṣẹ́ ibi, ó máa fẹ́ kí àkókò tó jìnnà wà láààrin òun àti iṣẹ́ ibi rẹ̀. Allāhu sì ń kìlọ̀ ara Rẹ̀ fún yín. Allāhu sì ni Aláàánú àwọn olùjọ́sìn.

Verse 31

قُلْ إِن كُنتُمْ تُحِبُّونَ ٱللَّهَ فَٱتَّبِعُونِى يُحْبِبْكُمُ ٱللَّهُ وَيَغْفِرْ لَكُمْ ذُنُوبَكُمْ ۗ وَٱللَّهُ غَفُورٌ رَّحِيمٌ

Transliteration qul in kuntum tuḥibbūna l-laha fa-ittabiʿūnī yuḥ'bib'kumu l-lahu wayaghfir lakum dhunūbakum wal-lahu ghafūrun raḥīmun

Yoruba Sọ pé: “Tí ẹ̀yin bá nífẹ̀ẹ́ Allāhu, ẹ tẹ̀lé mi, Allāhu máa nífẹ̀ẹ́ yín, Ó sì máa forí ẹ̀ṣẹ̀ yín jìn yín. Allāhu ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.

Verse 32

قُلْ أَطِيعُوا۟ ٱللَّهَ وَٱلرَّسُولَ ۖ فَإِن تَوَلَّوْا۟ فَإِنَّ ٱللَّهَ لَا يُحِبُّ ٱلْكَـٰفِرِينَ

Transliteration qul aṭīʿū l-laha wal-rasūla fa-in tawallaw fa-inna l-laha lā yuḥibbu l-kāfirīna

Yoruba Sọ pé: “Ẹ tẹ̀lé (ti) Allāhu àti Òjíṣẹ́. Tí ẹ bá sì pẹ̀yìn dà, dájúdájú Allāhu kò nífẹ̀ẹ́ àwọn aláìgbàgbọ́.

Verse 33

۞ إِنَّ ٱللَّهَ ٱصْطَفَىٰٓ ءَادَمَ وَنُوحًا وَءَالَ إِبْرَٰهِيمَ وَءَالَ عِمْرَٰنَ عَلَى ٱلْعَـٰلَمِينَ

Transliteration inna l-laha iṣ'ṭafā ādama wanūḥan waāla ib'rāhīma waāla ʿim'rāna ʿalā l-ʿālamīna

Yoruba Dájúdájú Allāhu ṣa Ādam, Nūh, ará ilé ’Ibrọ̄hīm àti ará ilé ‘Imrọ̄n lẹ́ṣà lórí àwọn ẹ̀dá (àsìkò tiwọn).

Verse 34

ذُرِّيَّةًۢ بَعْضُهَا مِنۢ بَعْضٍ ۗ وَٱللَّهُ سَمِيعٌ عَلِيمٌ

Transliteration dhurriyyatan baʿḍuhā min baʿḍin wal-lahu samīʿun ʿalīmun

Yoruba Wọ́n jẹ́ àrọ́mọdọ́mọ; apá kan wọn wá láti ara apá kan. Allāhu sì ni Olùgbọ́, Onímọ̀.

Verse 35

إِذْ قَالَتِ ٱمْرَأَتُ عِمْرَٰنَ رَبِّ إِنِّى نَذَرْتُ لَكَ مَا فِى بَطْنِى مُحَرَّرًا فَتَقَبَّلْ مِنِّىٓ ۖ إِنَّكَ أَنتَ ٱلسَّمِيعُ ٱلْعَلِيمُ

Transliteration idh qālati im'ra-atu ʿim'rāna rabbi innī nadhartu laka mā fī baṭnī muḥarraran fataqabbal minnī innaka anta l-samīʿu l-ʿalīmu

Yoruba (Ẹ rántí) nígbà tí aya ‘Imrọ̄n sọ pé: “Olúwa mi, dájúdájú èmi fi ohun tí ń bẹ nínú ikùn mi jẹ́jẹ̀ẹ́ fún Ọ (pé) mo máa yà á sọ́tọ̀ (fún ẹ̀sìn Rẹ). Nítorí náà, gbà á lọ́wọ́ mi, dájúdájú Ìwọ ni Olùgbọ́, Onímọ̀.”

Verse 36

فَلَمَّا وَضَعَتْهَا قَالَتْ رَبِّ إِنِّى وَضَعْتُهَآ أُنثَىٰ وَٱللَّهُ أَعْلَمُ بِمَا وَضَعَتْ وَلَيْسَ ٱلذَّكَرُ كَٱلْأُنثَىٰ ۖ وَإِنِّى سَمَّيْتُهَا مَرْيَمَ وَإِنِّىٓ أُعِيذُهَا بِكَ وَذُرِّيَّتَهَا مِنَ ٱلشَّيْطَـٰنِ ٱلرَّجِيمِ

Transliteration falammā waḍaʿathā qālat rabbi innī waḍaʿtuhā unthā wal-lahu aʿlamu bimā waḍaʿat walaysa l-dhakaru kal-unthā wa-innī sammaytuhā maryama wa-innī uʿīdhuhā bika wadhurriyyatahā mina l-shayṭāni l-rajīmi

Yoruba Nígbà tí ó bí i, ó sọ pé: “Olúwa mi, dájúdájú mo bí i ní obìnrin - Allāhu sì nímọ̀ jùlọ nípa ohun tí ó bí – ọkùnrin kò sì dà bí obìnrin. Dájúdájú èmi sọ ọ́ ní Mọryam. Àti pé dájúdájú mò ń fi Ọ́ wá ààbò fún òun àti àrọ́mọdọ́mọ rẹ̀ lọ́dọ̀ Èṣù ẹni ẹ̀kọ̀.”

Verse 37

فَتَقَبَّلَهَا رَبُّهَا بِقَبُولٍ حَسَنٍ وَأَنۢبَتَهَا نَبَاتًا حَسَنًا وَكَفَّلَهَا زَكَرِيَّا ۖ كُلَّمَا دَخَلَ عَلَيْهَا زَكَرِيَّا ٱلْمِحْرَابَ وَجَدَ عِندَهَا رِزْقًا ۖ قَالَ يَـٰمَرْيَمُ أَنَّىٰ لَكِ هَـٰذَا ۖ قَالَتْ هُوَ مِنْ عِندِ ٱللَّهِ ۖ إِنَّ ٱللَّهَ يَرْزُقُ مَن يَشَآءُ بِغَيْرِ حِسَابٍ

Transliteration fataqabbalahā rabbuhā biqabūlin ḥasanin wa-anbatahā nabātan ḥasanan wakaffalahā zakariyyā kullamā dakhala ʿalayhā zakariyyā l-miḥ'rāba wajada ʿindahā riz'qan qāla yāmaryamu annā laki hādhā qālat huwa min ʿindi l-lahi inna l-laha yarzuqu man yashāu bighayri ḥisābin

Yoruba Olúwa rẹ̀ sì gba àdúà rẹ̀ ní gbígbà dáadáa. Ó sì mú ọmọ náà dàgbà ní ìdàgbà dáadáa. Ó sì fi Zakariyyā ṣe alágbàtọ́ rẹ̀. Ìgbàkígbà tí Zakariyyā bá wọlé tọ̀ ọ́ nínú ilé ìjọ́sìn, ó máa bá èsè (èso) lọ́dọ̀ rẹ̀. (Zakariyyā á) sọ pé: “Mọryam, báwo ni èyí ṣe jẹ́ tìrẹ?” (Mọryam á) sọ pé: “Ó wá láti ọ̀dọ̀ Allāhu. Dájúdájú Allāhu ń pèsè ìjẹ-ìmu àti ìgbádùn fún ẹni tí Ó bá fẹ́ láì níí ní ìṣírò.”1

Verse 38

هُنَالِكَ دَعَا زَكَرِيَّا رَبَّهُۥ ۖ قَالَ رَبِّ هَبْ لِى مِن لَّدُنكَ ذُرِّيَّةً طَيِّبَةً ۖ إِنَّكَ سَمِيعُ ٱلدُّعَآءِ

Transliteration hunālika daʿā zakariyyā rabbahu qāla rabbi hab lī min ladunka dhurriyyatan ṭayyibatan innaka samīʿu l-duʿāi

Yoruba Ibẹ̀yẹn ni Zakariyyā ti pe Olúwa rẹ̀. Ó sọ pé: “Olúwa mi, ta mí ní ọrẹ àrọ́mọdọ́mọ dáadáa láti ọ̀dọ̀ Rẹ. Dájúdájú Ìwọ ni Olùgbọ́-àdúà.”

Verse 39

فَنَادَتْهُ ٱلْمَلَـٰٓئِكَةُ وَهُوَ قَآئِمٌ يُصَلِّى فِى ٱلْمِحْرَابِ أَنَّ ٱللَّهَ يُبَشِّرُكَ بِيَحْيَىٰ مُصَدِّقًۢا بِكَلِمَةٍ مِّنَ ٱللَّهِ وَسَيِّدًا وَحَصُورًا وَنَبِيًّا مِّنَ ٱلصَّـٰلِحِينَ

Transliteration fanādathu l-malāikatu wahuwa qāimun yuṣallī fī l-miḥ'rābi anna l-laha yubashiruka biyaḥyā muṣaddiqan bikalimatin mina l-lahi wasayyidan waḥaṣūran wanabiyyan mina l-ṣāliḥīna

Yoruba Nítorí náà, àwọn mọlāika pè é nígbà tí ó ń kírun lọ́wọ́ nínú ilé ìjọ́sìn, (wọ́n sọ pé): “Dájúdájú Allāhu ń fún ọ ní ìró ìdùnnú nípa (bíbí) Yahyā. Ó máa fi òdodo rinlẹ̀ nípa ọ̀rọ̀ kan láti ọ̀dọ̀ Allāhu.(Ó máa jẹ́) aṣíwájú, tí kò kúndùn obìnrin.2 (Ó máa jẹ́) Ànábì. Ó sì wà nínú àwọn ẹni rere.”

Verse 40

قَالَ رَبِّ أَنَّىٰ يَكُونُ لِى غُلَـٰمٌ وَقَدْ بَلَغَنِىَ ٱلْكِبَرُ وَٱمْرَأَتِى عَاقِرٌ ۖ قَالَ كَذَٰلِكَ ٱللَّهُ يَفْعَلُ مَا يَشَآءُ

Transliteration qāla rabbi annā yakūnu lī ghulāmun waqad balaghaniya l-kibaru wa-im'ra-atī ʿāqirun qāla kadhālika l-lahu yafʿalu mā yashāu

Yoruba (Zakariyyā) sọ pé: “Olúwa mi, báwo ni èmi yóò ṣe ní ọmọkùnrin; mo mà ti dàgbàlágbà, àgàn sì ni obìnrin mi?” (Mọlāika) sọ pé: “Báyẹn ni Allāhu ṣe ń ṣe ohun tí Ó bá fẹ́.”

Verse 41

قَالَ رَبِّ ٱجْعَل لِّىٓ ءَايَةً ۖ قَالَ ءَايَتُكَ أَلَّا تُكَلِّمَ ٱلنَّاسَ ثَلَـٰثَةَ أَيَّامٍ إِلَّا رَمْزًا ۗ وَٱذْكُر رَّبَّكَ كَثِيرًا وَسَبِّحْ بِٱلْعَشِىِّ وَٱلْإِبْكَـٰرِ

Transliteration qāla rabbi ij'ʿal lī āyatan qāla āyatuka allā tukallima l-nāsa thalāthata ayyāmin illā ramzan wa-udh'kur rabbaka kathīran wasabbiḥ bil-ʿashiyi wal-ib'kāri

Yoruba (Zakariyyā) sọ pé: “Olúwa mi, fún mi ní àmì kan.” (Mọlāika) sọ pé: “Àmì rẹ ni pé ìwọ kò níí lè bá ènìyàn sọ̀rọ̀ fún ọjọ́ mẹ́ta àyàfi títọ́ka (sí n̄ǹkan). Rántí Olúwa rẹ lọ́pọ̀lọ́pọ̀. Kí o sì ṣàfọ̀mọ́ (fún Un) ní àṣálẹ́ àti ní òwúrọ̀ kùtù.”

Verse 42

وَإِذْ قَالَتِ ٱلْمَلَـٰٓئِكَةُ يَـٰمَرْيَمُ إِنَّ ٱللَّهَ ٱصْطَفَىٰكِ وَطَهَّرَكِ وَٱصْطَفَىٰكِ عَلَىٰ نِسَآءِ ٱلْعَـٰلَمِينَ

Transliteration wa-idh qālati l-malāikatu yāmaryamu inna l-laha iṣ'ṭafāki waṭahharaki wa-iṣ'ṭafāki ʿalā nisāi l-ʿālamīna

Yoruba (Ẹ rántí) nígbà tí àwọn mọlāika sọ pé: “Mọryam, dájúdájú Allāhu ṣà ọ́ lẹ́ṣà. Ó fọ̀ ọ́ mọ́. Ó sì ṣà ọ́ lẹ́ṣà lórí àwọn obìnrin ayé (àsìkò tìrẹ).1

Verse 43

يَـٰمَرْيَمُ ٱقْنُتِى لِرَبِّكِ وَٱسْجُدِى وَٱرْكَعِى مَعَ ٱلرَّٰكِعِينَ

Transliteration yāmaryamu uq'nutī lirabbiki wa-us'judī wa-ir'kaʿī maʿa l-rākiʿīna

Yoruba Mọryam, tẹ̀lé àṣẹ Olúwa rẹ. Forí kanlẹ̀ fún Un. Kí o sì dáwọ́tẹ orúnkún pẹ̀lú àwọn olùdáwọ́tẹ-orúnkún (lórí ìrun).

Verse 44

ذَٰلِكَ مِنْ أَنۢبَآءِ ٱلْغَيْبِ نُوحِيهِ إِلَيْكَ ۚ وَمَا كُنتَ لَدَيْهِمْ إِذْ يُلْقُونَ أَقْلَـٰمَهُمْ أَيُّهُمْ يَكْفُلُ مَرْيَمَ وَمَا كُنتَ لَدَيْهِمْ إِذْ يَخْتَصِمُونَ

Transliteration dhālika min anbāi l-ghaybi nūḥīhi ilayka wamā kunta ladayhim idh yul'qūna aqlāmahum ayyuhum yakfulu maryama wamā kunta ladayhim idh yakhtaṣimūna

Yoruba Ìyẹn wà nínú ìró ìkọ̀kọ̀ tí À ń fi ìmísí rẹ̀ ránṣẹ́ sí ọ. Ìwọ kò kúkú sí lọ́dọ̀ wọn nígbà tí wọ́n ń ju gègé wọn (sínú odò láti mọ) ta ni nínú wọn ni ó máa gba Mọryam wò.Ìwọ kò sì sí lọ́dọ̀ wọn nígbà tí wọ́n ń ṣe ìfàn̄fà (lórí rẹ̀).

Verse 45

إِذْ قَالَتِ ٱلْمَلَـٰٓئِكَةُ يَـٰمَرْيَمُ إِنَّ ٱللَّهَ يُبَشِّرُكِ بِكَلِمَةٍ مِّنْهُ ٱسْمُهُ ٱلْمَسِيحُ عِيسَى ٱبْنُ مَرْيَمَ وَجِيهًا فِى ٱلدُّنْيَا وَٱلْـَٔاخِرَةِ وَمِنَ ٱلْمُقَرَّبِينَ

Transliteration idh qālati l-malāikatu yāmaryamu inna l-laha yubashiruki bikalimatin min'hu us'muhu l-masīḥu ʿīsā ub'nu maryama wajīhan fī l-dun'yā wal-ākhirati wamina l-muqarabīna

Yoruba (Ẹ rántí) nígbà tí àwọn mọlāikasọ pé: “Mọryam, dájúdájú Allāhu ń fún ọ ní ìró ìdùnnú (nípa dídá ẹ̀dá kan pẹ̀lú) ọ̀rọ̀ kan láti ọ̀dọ̀ Rẹ̀. Orúkọ rẹ̀ ni Mọsīh ‘Īsā ọmọ Mọryam. Ẹni iyì ni ní ayé àti ní ọ̀run.2 Ó sì wà lára alásùn-únmọ́ (Allāhu).

Verse 46

وَيُكَلِّمُ ٱلنَّاسَ فِى ٱلْمَهْدِ وَكَهْلًا وَمِنَ ٱلصَّـٰلِحِينَ

Transliteration wayukallimu l-nāsa fī l-mahdi wakahlan wamina l-ṣāliḥīna

Yoruba Ó máa bá àwọn ènìyàn sọ̀rọ̀ lórí ìtẹ́ ní òpóǹló àti nígbà tó bá dàgbà.Ó sì wà nínú àwọn ẹni rere.”

Verse 47

قَالَتْ رَبِّ أَنَّىٰ يَكُونُ لِى وَلَدٌ وَلَمْ يَمْسَسْنِى بَشَرٌ ۖ قَالَ كَذَٰلِكِ ٱللَّهُ يَخْلُقُ مَا يَشَآءُ ۚ إِذَا قَضَىٰٓ أَمْرًا فَإِنَّمَا يَقُولُ لَهُۥ كُن فَيَكُونُ

Transliteration qālat rabbi annā yakūnu lī waladun walam yamsasnī basharun qāla kadhāliki l-lahu yakhluqu mā yashāu idhā qaḍā amran fa-innamā yaqūlu lahu kun fayakūnu

Yoruba (Mọryam) sọ pé: “Olúwa mi báwo ni èmi yó ṣe ní ọmọkùnrin, (nígbà tí) abara kan kò fọwọ́ kàn mí.” Ó sọ pé: Báyẹn ni Allāhu ṣe ń dá ohun tí Ó bá fẹ́. Nígbà tí Ó bá (gbèrò) láti dá ẹ̀dá kan ohun tí Ó máa sọ fún un ni pé: “Jẹ́ bẹ́ẹ̀.” Ó sì máa jẹ́ bẹ́ẹ̀.

Verse 48

وَيُعَلِّمُهُ ٱلْكِتَـٰبَ وَٱلْحِكْمَةَ وَٱلتَّوْرَىٰةَ وَٱلْإِنجِيلَ

Transliteration wayuʿallimuhu l-kitāba wal-ḥik'mata wal-tawrāta wal-injīla

Yoruba (Allāhu) yóò fún un ní ìmọ̀ ìkọ̀wé, òye ìjìnlẹ̀, at-Taorāh àti al-’Injīl.

Verse 49

وَرَسُولًا إِلَىٰ بَنِىٓ إِسْرَٰٓءِيلَ أَنِّى قَدْ جِئْتُكُم بِـَٔايَةٍ مِّن رَّبِّكُمْ ۖ أَنِّىٓ أَخْلُقُ لَكُم مِّنَ ٱلطِّينِ كَهَيْـَٔةِ ٱلطَّيْرِ فَأَنفُخُ فِيهِ فَيَكُونُ طَيْرًۢا بِإِذْنِ ٱللَّهِ ۖ وَأُبْرِئُ ٱلْأَكْمَهَ وَٱلْأَبْرَصَ وَأُحْىِ ٱلْمَوْتَىٰ بِإِذْنِ ٱللَّهِ ۖ وَأُنَبِّئُكُم بِمَا تَأْكُلُونَ وَمَا تَدَّخِرُونَ فِى بُيُوتِكُمْ ۚ إِنَّ فِى ذَٰلِكَ لَـَٔايَةً لَّكُمْ إِن كُنتُم مُّؤْمِنِينَ

Transliteration warasūlan ilā banī is'rāīla annī qad ji'tukum biāyatin min rabbikum annī akhluqu lakum mina l-ṭīni kahayati l-ṭayri fa-anfukhu fīhi fayakūnu ṭayran bi-idh'ni l-lahi wa-ub'ri-u l-akmaha wal-abraṣa wa-uḥ'yī l-mawtā bi-idh'ni l-lahi wa-unabbi-ukum bimā takulūna wamā taddakhirūna fī buyūtikum inna fī dhālika laāyatan lakum in kuntum mu'minīna

Yoruba (Ó sì jẹ́) Òjíṣẹ́ (tí A rán níṣẹ́) sí àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl. (Ó sì máa sọ fún wọn pé) “Dájúdájú èmi ti mú àmì kan wá fún yín láti ọ̀dọ̀ Olúwa yín. Dájúdájú èmi yóò mọ n̄ǹkan fún yín láti inú amọ̀ bí ìrísí ẹyẹ. Èmi yóò fẹ́ atẹ́gùn sínú rẹ̀. Ó sì máa di ẹyẹ pẹ̀lú ìyọ̀ǹda Allāhu. Èmi yóò ṣe ìwòsàn fún afọ́jú àti adẹ́tẹ̀, mo sì máa sọ òkú di alààyè pẹ̀lú ìyọ̀ǹda Allāhu. Èmi yóò máa fún yín ní ìró ohun tí ẹ̀ ń jẹ àti ohun tí ẹ̀ ń fi pamọ́ sínú ilé yín. Dájúdájú àmì kan wà nínú ìyẹn fún yín, tí ẹ bá jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo.1

Verse 50

وَمُصَدِّقًا لِّمَا بَيْنَ يَدَىَّ مِنَ ٱلتَّوْرَىٰةِ وَلِأُحِلَّ لَكُم بَعْضَ ٱلَّذِى حُرِّمَ عَلَيْكُمْ ۚ وَجِئْتُكُم بِـَٔايَةٍ مِّن رَّبِّكُمْ فَٱتَّقُوا۟ ٱللَّهَ وَأَطِيعُونِ

Transliteration wamuṣaddiqan limā bayna yadayya mina l-tawrāti wali-uḥilla lakum baʿḍa alladhī ḥurrima ʿalaykum waji'tukum biāyatin min rabbikum fa-ittaqū l-laha wa-aṭīʿūni

Yoruba Mo sì ń fi ohun tó jẹ́ òdodo rinlẹ̀ nípa èyí tó ṣíwájú mi nínú at-Taorāh nítorí kí èmi lè ṣe apá kan èyí tí wọ́n ṣe ní èèwọ̀ fún yín ní ẹ̀tọ́ fún yín. Mo ti mú àmì kan wá fún yín láti ọ̀dọ̀ Olúwa yín. Nítorí náà, ẹ bẹ̀rù Allāhu, kí ẹ sì tẹ̀lé mi.

Verse 51

إِنَّ ٱللَّهَ رَبِّى وَرَبُّكُمْ فَٱعْبُدُوهُ ۗ هَـٰذَا صِرَٰطٌ مُّسْتَقِيمٌ

Transliteration inna l-laha rabbī warabbukum fa-uʿ'budūhu hādhā ṣirāṭun mus'taqīmun

Yoruba Dájúdájú Allāhu ni Olúwa mi àti Olúwa yín. Nítorí náà, ẹ jọ́sìn fún Un. Èyí ni ọ̀nà tààrà.”

Verse 52

۞ فَلَمَّآ أَحَسَّ عِيسَىٰ مِنْهُمُ ٱلْكُفْرَ قَالَ مَنْ أَنصَارِىٓ إِلَى ٱللَّهِ ۖ قَالَ ٱلْحَوَارِيُّونَ نَحْنُ أَنصَارُ ٱللَّهِ ءَامَنَّا بِٱللَّهِ وَٱشْهَدْ بِأَنَّا مُسْلِمُونَ

Transliteration falammā aḥassa ʿīsā min'humu l-kuf'ra qāla man anṣārī ilā l-lahi qāla l-ḥawāriyūna naḥnu anṣāru l-lahi āmannā bil-lahi wa-ish'had bi-annā mus'limūna

Yoruba Nígbà tí (Ànábì) ‘Īsā fura sí àìgbàgbọ́ lọ́dọ̀ wọn (pé wọ́n fẹ́ pa òun), ó sọ pé: “Ta ni olùrànlọ́wọ́ mi sí ọ̀dọ̀ Allāhu?” Àwọn ọmọlẹ́yìn (rẹ̀) sọ pé: “Àwa ni olùrànlọ́wọ́ fún (ẹ̀sìn) Allāhu. A gba Allāhu gbọ́. Kí o sì jẹ́rìí pé dájúdájú mùsùlùmí ni wá.

Verse 53

رَبَّنَآ ءَامَنَّا بِمَآ أَنزَلْتَ وَٱتَّبَعْنَا ٱلرَّسُولَ فَٱكْتُبْنَا مَعَ ٱلشَّـٰهِدِينَ

Transliteration rabbanā āmannā bimā anzalta wa-ittabaʿnā l-rasūla fa-uk'tub'nā maʿa l-shāhidīna

Yoruba Olúwa wa, a gbàgbọ́ nínú ohun tí O sọ̀kalẹ̀. A sì tẹ̀lé Òjíṣẹ́. Nítorí náà, kọ wá mọ́ àwọn olùjẹ́rìí.”

Verse 54

وَمَكَرُوا۟ وَمَكَرَ ٱللَّهُ ۖ وَٱللَّهُ خَيْرُ ٱلْمَـٰكِرِينَ

Transliteration wamakarū wamakara l-lahu wal-lahu khayru l-mākirīna

Yoruba Wọ́n déte, Allāhu sì déte. Allāhu sì l’óore jùlọ nínú àwọn adéte.1

Verse 55

إِذْ قَالَ ٱللَّهُ يَـٰعِيسَىٰٓ إِنِّى مُتَوَفِّيكَ وَرَافِعُكَ إِلَىَّ وَمُطَهِّرُكَ مِنَ ٱلَّذِينَ كَفَرُوا۟ وَجَاعِلُ ٱلَّذِينَ ٱتَّبَعُوكَ فَوْقَ ٱلَّذِينَ كَفَرُوٓا۟ إِلَىٰ يَوْمِ ٱلْقِيَـٰمَةِ ۖ ثُمَّ إِلَىَّ مَرْجِعُكُمْ فَأَحْكُمُ بَيْنَكُمْ فِيمَا كُنتُمْ فِيهِ تَخْتَلِفُونَ

Transliteration idh qāla l-lahu yāʿīsā innī mutawaffīka warāfiʿuka ilayya wamuṭahhiruka mina alladhīna kafarū wajāʿilu alladhīna ittabaʿūka fawqa alladhīna kafarū ilā yawmi l-qiyāmati thumma ilayya marjiʿukum fa-aḥkumu baynakum fīmā kuntum fīhi takhtalifūna

Yoruba (Ẹ rántí) nígbà tí Allāhu sọ pé: “‘Īsā, dájúdájú Mo máa gbà ọ́ kúrò lọ́wọ́ wọn pátápátá.Mo máa gbé ọ wá sókè lọ́dọ̀ Mi. Mo sì máa fọ̀ ọ́ mọ́ lọ́dọ̀ àwọn tó ṣàì gbàgbọ́.2 Mo sì máa fi àwọn tó tẹ̀lé ọ borí àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ títí di Ọjọ́ Àjíǹde. Lẹ́yìn náà, ọ̀dọ̀ Mi ni ibùpadàsí yín. Mo sì máa ṣe ìdájọ́ láààrin yín nípa ohun tí ẹ̀ ń yapa ẹnu sí.

Verse 56

فَأَمَّا ٱلَّذِينَ كَفَرُوا۟ فَأُعَذِّبُهُمْ عَذَابًا شَدِيدًا فِى ٱلدُّنْيَا وَٱلْـَٔاخِرَةِ وَمَا لَهُم مِّن نَّـٰصِرِينَ

Transliteration fa-ammā alladhīna kafarū fa-uʿadhibuhum ʿadhāban shadīdan fī l-dun'yā wal-ākhirati wamā lahum min nāṣirīna

Yoruba Ní ti àwọn tó ṣàì gbàgbọ́, Èmi yóò jẹ wọ́n níyà líle ní ayé àti ní ọ̀run. Kò sì níí sí àwọn olùrànlọ́wọ́ fún wọn.

Verse 57

وَأَمَّا ٱلَّذِينَ ءَامَنُوا۟ وَعَمِلُوا۟ ٱلصَّـٰلِحَـٰتِ فَيُوَفِّيهِمْ أُجُورَهُمْ ۗ وَٱللَّهُ لَا يُحِبُّ ٱلظَّـٰلِمِينَ

Transliteration wa-ammā alladhīna āmanū waʿamilū l-ṣāliḥāti fayuwaffīhim ujūrahum wal-lahu lā yuḥibbu l-ẓālimīna

Yoruba Ní ti àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe àwọn iṣẹ́ rere, (Allāhu) máa fún wọn ní ẹ̀san wọn ní kíkún. Allāhu kò sì fẹ́ràn àwọn alábòsí.

Verse 58

ذَٰلِكَ نَتْلُوهُ عَلَيْكَ مِنَ ٱلْـَٔايَـٰتِ وَٱلذِّكْرِ ٱلْحَكِيمِ

Transliteration dhālika natlūhu ʿalayka mina l-āyāti wal-dhik'ri l-ḥakīmi

Yoruba Ìyẹn ni À ń ké fún ọ nínú àwọn āyah àti ìrántí tí ó kún fún òye ìjìnlẹ̀(ìyẹn, al-Ƙur’ān).

Verse 59

إِنَّ مَثَلَ عِيسَىٰ عِندَ ٱللَّهِ كَمَثَلِ ءَادَمَ ۖ خَلَقَهُۥ مِن تُرَابٍ ثُمَّ قَالَ لَهُۥ كُن فَيَكُونُ

Transliteration inna mathala ʿīsā ʿinda l-lahi kamathali ādama khalaqahu min turābin thumma qāla lahu kun fayakūnu

Yoruba Dájúdájú irú ‘Īsā lọ́dọ̀ Allāhu dà bí irú Ādam; (Allāhu) dá a láti ara erùpẹ̀. Lẹ́yìn náà, Ó sọ pé: “Jẹ́ bẹ́ẹ̀.” Ó sì jẹ́ bẹ́ẹ̀.1

Verse 60

ٱلْحَقُّ مِن رَّبِّكَ فَلَا تَكُن مِّنَ ٱلْمُمْتَرِينَ

Transliteration al-ḥaqu min rabbika falā takun mina l-mum'tarīna

Yoruba Òdodo ni láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ. Nítorí náà, má ṣe wà nínú àwọn oníyèméjì.

Verse 61

فَمَنْ حَآجَّكَ فِيهِ مِنۢ بَعْدِ مَا جَآءَكَ مِنَ ٱلْعِلْمِ فَقُلْ تَعَالَوْا۟ نَدْعُ أَبْنَآءَنَا وَأَبْنَآءَكُمْ وَنِسَآءَنَا وَنِسَآءَكُمْ وَأَنفُسَنَا وَأَنفُسَكُمْ ثُمَّ نَبْتَهِلْ فَنَجْعَل لَّعْنَتَ ٱللَّهِ عَلَى ٱلْكَـٰذِبِينَ

Transliteration faman ḥājjaka fīhi min baʿdi mā jāaka mina l-ʿil'mi faqul taʿālaw nadʿu abnāanā wa-abnāakum wanisāanā wanisāakum wa-anfusanā wa-anfusakum thumma nabtahil fanajʿal laʿnata l-lahi ʿalā l-kādhibīna

Yoruba Nítorí náà, ẹnikẹ́ni tí ó bá jà ọ́ níyàn nípa rẹ̀ lẹ́yìn ohun tí ó dé bá ọ nínú ìmọ̀, kí o sọ pé: “Ẹ wá! Kí á pe àwọn ọmọkùnrin wa àti àwọn ọmọkùnrin yín àti àwọn obìnrin wa àti àwọn obìnrin yín àti àwa àti ẹ̀yin náà. Lẹ́yìn náà, kí á ṣàdúà ìparun (lórí òpùrọ́ nínú wa). Nítorí náà, a óò sọ pé, “ibi dandan (ìgbéjìnnà sí ìkẹ́) Allāhu kí ó máa jẹ́ ti àwọn òpùrọ́.”1

Verse 62

إِنَّ هَـٰذَا لَهُوَ ٱلْقَصَصُ ٱلْحَقُّ ۚ وَمَا مِنْ إِلَـٰهٍ إِلَّا ٱللَّهُ ۚ وَإِنَّ ٱللَّهَ لَهُوَ ٱلْعَزِيزُ ٱلْحَكِيمُ

Transliteration inna hādhā lahuwa l-qaṣaṣu l-ḥaqu wamā min ilāhin illā l-lahu wa-inna l-laha lahuwa l-ʿazīzu l-ḥakīmu

Yoruba Dájúdájú èyí, òhun ni ìtàn òdodo. Àti pé kò sí ọlọ́hun kan tí a gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo àyàfi Allāhu. Dájúdájú Allāhu, Òun ni Alágbára, Ọlọ́gbọ́n.

Verse 63

فَإِن تَوَلَّوْا۟ فَإِنَّ ٱللَّهَ عَلِيمٌۢ بِٱلْمُفْسِدِينَ

Transliteration fa-in tawallaw fa-inna l-laha ʿalīmun bil-muf'sidīna

Yoruba Tí wọ́n bá sì pẹ̀yìndà (kúrò níbi òdodo), dájúdájú Allāhu ni Onímọ̀ nípa àwọn òbìlẹ̀jẹ́.

Verse 64

قُلْ يَـٰٓأَهْلَ ٱلْكِتَـٰبِ تَعَالَوْا۟ إِلَىٰ كَلِمَةٍ سَوَآءٍۭ بَيْنَنَا وَبَيْنَكُمْ أَلَّا نَعْبُدَ إِلَّا ٱللَّهَ وَلَا نُشْرِكَ بِهِۦ شَيْـًٔا وَلَا يَتَّخِذَ بَعْضُنَا بَعْضًا أَرْبَابًا مِّن دُونِ ٱللَّهِ ۚ فَإِن تَوَلَّوْا۟ فَقُولُوا۟ ٱشْهَدُوا۟ بِأَنَّا مُسْلِمُونَ

Transliteration qul yāahla l-kitābi taʿālaw ilā kalimatin sawāin baynanā wabaynakum allā naʿbuda illā l-laha walā nush'rika bihi shayan walā yattakhidha baʿḍunā baʿḍan arbāban min dūni l-lahi fa-in tawallaw faqūlū ish'hadū bi-annā mus'limūna

Yoruba Sọ pé: “Ẹ̀yin onítírà, ẹ wá síbi ọ̀rọ̀ kan tó dọ́gba láààrin àwa àti ẹ̀yin, pé a ò níí jọ́sìn fún ẹnì kan àfi Allāhu. A ò sì níí fi kiní kan wá akẹgbẹ́ fún Un. Àti pé apá kan wa kò níí sọ apá kan di olúwa lẹ́yìn Allāhu.” Tí wọ́n bá sì gbúnrí, ẹ sọ pé: “Ẹ jẹ́rìí pé dájúdájú mùsùlùmí ni àwa.” 1

Verse 65

يَـٰٓأَهْلَ ٱلْكِتَـٰبِ لِمَ تُحَآجُّونَ فِىٓ إِبْرَٰهِيمَ وَمَآ أُنزِلَتِ ٱلتَّوْرَىٰةُ وَٱلْإِنجِيلُ إِلَّا مِنۢ بَعْدِهِۦٓ ۚ أَفَلَا تَعْقِلُونَ

Transliteration yāahla l-kitābi lima tuḥājjūna fī ib'rāhīma wamā unzilati l-tawrātu wal-injīlu illā min baʿdihi afalā taʿqilūna

Yoruba Ẹ̀yin onítírà, nítorí kí ni ẹ óò fi jiyàn nípa (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm? A kò sì sọ at-Taorāh àti al-’Injīl kalẹ̀ bí kò ṣe lẹ́yìn rẹ̀, ṣé ẹ kò ṣe làákàyè ni?

Verse 66

هَـٰٓأَنتُمْ هَـٰٓؤُلَآءِ حَـٰجَجْتُمْ فِيمَا لَكُم بِهِۦ عِلْمٌ فَلِمَ تُحَآجُّونَ فِيمَا لَيْسَ لَكُم بِهِۦ عِلْمٌ ۚ وَٱللَّهُ يَعْلَمُ وَأَنتُمْ لَا تَعْلَمُونَ

Transliteration hāantum hāulāi ḥājajtum fīmā lakum bihi ʿil'mun falima tuḥājjūna fīmā laysa lakum bihi ʿil'mun wal-lahu yaʿlamu wa-antum lā taʿlamūna

Yoruba Ẹ̀yin ni ìwọ̀nyí tí ẹ̀ ń jiyàn nípa ohun tí ẹ nímọ̀ nípa rẹ̀! Kí ni ó tún ń mu yín jiyàn nípa ohun tí ẹ ò nímọ̀ nípa rẹ̀?Allāhu nímọ̀. Ẹ̀yin kò sì nímọ̀.

Verse 67

مَا كَانَ إِبْرَٰهِيمُ يَهُودِيًّا وَلَا نَصْرَانِيًّا وَلَـٰكِن كَانَ حَنِيفًا مُّسْلِمًا وَمَا كَانَ مِنَ ٱلْمُشْرِكِينَ

Transliteration mā kāna ib'rāhīmu yahūdiyyan walā naṣrāniyyan walākin kāna ḥanīfan mus'liman wamā kāna mina l-mush'rikīna

Yoruba (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm kì í ṣe yẹhudi, kì í ṣe nasọ̄rọ̄, ṣùgbọ́n ó jẹ́ olùdúró-déédé, mùsùlùmí. Kò sì sí nínú àwọn ọ̀ṣẹbọ.

Verse 68

إِنَّ أَوْلَى ٱلنَّاسِ بِإِبْرَٰهِيمَ لَلَّذِينَ ٱتَّبَعُوهُ وَهَـٰذَا ٱلنَّبِىُّ وَٱلَّذِينَ ءَامَنُوا۟ ۗ وَٱللَّهُ وَلِىُّ ٱلْمُؤْمِنِينَ

Transliteration inna awlā l-nāsi bi-ib'rāhīma lalladhīna ittabaʿūhu wahādhā l-nabiyu wa-alladhīna āmanū wal-lahu waliyyu l-mu'minīna

Yoruba Dájúdájú àwọn ènìyàn tó súnmọ́ (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm jùlọ (nínú ẹ̀sìn ’Islām) ni àwọn tó tẹ̀lé e àti Ànábì yìí - kí ìkẹ́ àti ọlà máa bá a - àti àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo (ìyẹn, àwọn mùsùlùmí). Allāhu ni Alátìlẹ́yìn fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo.

Verse 69

وَدَّت طَّآئِفَةٌ مِّنْ أَهْلِ ٱلْكِتَـٰبِ لَوْ يُضِلُّونَكُمْ وَمَا يُضِلُّونَ إِلَّآ أَنفُسَهُمْ وَمَا يَشْعُرُونَ

Transliteration waddat ṭāifatun min ahli l-kitābi law yuḍillūnakum wamā yuḍillūna illā anfusahum wamā yashʿurūna

Yoruba Igun kan nínú àwọn onítírà fẹ́ láti ṣì yín lọ́nà. Wọn kò lè ṣi ẹnikẹ́ni lọ́nà àfi ara wọn, wọn kò sì fura.

Verse 70

يَـٰٓأَهْلَ ٱلْكِتَـٰبِ لِمَ تَكْفُرُونَ بِـَٔايَـٰتِ ٱللَّهِ وَأَنتُمْ تَشْهَدُونَ

Transliteration yāahla l-kitābi lima takfurūna biāyāti l-lahi wa-antum tashhadūna

Yoruba Ẹ̀yin onítírà, nítorí kí ni ẹ óò fi ṣàì gbàgbọ́ nínú àwọn āyah Allāhu, ẹ sì ń jẹ́rìí (sí òdodo rẹ̀)!

Verse 71

يَـٰٓأَهْلَ ٱلْكِتَـٰبِ لِمَ تَلْبِسُونَ ٱلْحَقَّ بِٱلْبَـٰطِلِ وَتَكْتُمُونَ ٱلْحَقَّ وَأَنتُمْ تَعْلَمُونَ

Transliteration yāahla l-kitābi lima talbisūna l-ḥaqa bil-bāṭili wataktumūna l-ḥaqa wa-antum taʿlamūna

Yoruba Ẹ̀yin onítírà, nítorí kí ni ẹ óò fi da irọ́ pọ̀ mọ́ òdodo, ẹ sì ń fi òdodo pamọ́ nígbà tí ẹ̀yin mọ (òdodo)?

Verse 72

وَقَالَت طَّآئِفَةٌ مِّنْ أَهْلِ ٱلْكِتَـٰبِ ءَامِنُوا۟ بِٱلَّذِىٓ أُنزِلَ عَلَى ٱلَّذِينَ ءَامَنُوا۟ وَجْهَ ٱلنَّهَارِ وَٱكْفُرُوٓا۟ ءَاخِرَهُۥ لَعَلَّهُمْ يَرْجِعُونَ

Transliteration waqālat ṭāifatun min ahli l-kitābi āminū bi-alladhī unzila ʿalā alladhīna āmanū wajha l-nahāri wa-uk'furū ākhirahu laʿallahum yarjiʿūna

Yoruba Igun kan nínú àwọn onítírà wí pé: “Ẹ lọ gbàgbọ́ nínú ohun tí Wọ́n sọ̀kalẹ̀ fún àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo níbẹ̀rẹ̀ ọjọ́, kí ẹ sì takò ó níparí rẹ̀, bóyá àwọn mùsùlùmí (kan) máa ṣẹ́rí padà (sẹ́yìn nínú ẹ̀sìn ’Islām).1

Verse 73

وَلَا تُؤْمِنُوٓا۟ إِلَّا لِمَن تَبِعَ دِينَكُمْ قُلْ إِنَّ ٱلْهُدَىٰ هُدَى ٱللَّهِ أَن يُؤْتَىٰٓ أَحَدٌ مِّثْلَ مَآ أُوتِيتُمْ أَوْ يُحَآجُّوكُمْ عِندَ رَبِّكُمْ ۗ قُلْ إِنَّ ٱلْفَضْلَ بِيَدِ ٱللَّهِ يُؤْتِيهِ مَن يَشَآءُ ۗ وَٱللَّهُ وَٰسِعٌ عَلِيمٌ

Transliteration walā tu'minū illā liman tabiʿa dīnakum qul inna l-hudā hudā l-lahi an yu'tā aḥadun mith'la mā ūtītum aw yuḥājjūkum ʿinda rabbikum qul inna l-faḍla biyadi l-lahi yu'tīhi man yashāu wal-lahu wāsiʿun ʿalīmun

Yoruba (Wọ́n tún wí pé:) “Ẹ má gbàgbọ́ àyàfi ẹni tí ó bá tẹ̀lé ẹ̀sìn yín.” Sọ pé: “Dájúdájú ìmọ̀nà (’Islām) ni ìmọ̀nà ti Allāhu.” (Wọ́n tún wí pé:) “(Ẹ má gbàgbọ́) pé wọ́n fún ẹnì kan ní irú ohun tí wọ́n fún yín tàbí pé wọn yóò takò yín (tí wọn yó sì jàre yín) lọ́dọ̀ Olúwa yín.” Sọ pé: “Dájúdájú oore àjùlọ wà ní ọwọ́ Allāhu. Ó ń fún ẹni tí Ó bá fẹ́. Allāhu ni Olùgbààyè, Onímọ̀.”

Verse 74

يَخْتَصُّ بِرَحْمَتِهِۦ مَن يَشَآءُ ۗ وَٱللَّهُ ذُو ٱلْفَضْلِ ٱلْعَظِيمِ

Transliteration yakhtaṣṣu biraḥmatihi man yashāu wal-lahu dhū l-faḍli l-ʿaẓīmi

Yoruba (Allāhu) ń fi ìkẹ́ Rẹ̀ṣa ẹni tí Ó bá fẹ́ lẹ́ṣà. Allāhu ni Olóore ńlá.

Verse 75

۞ وَمِنْ أَهْلِ ٱلْكِتَـٰبِ مَنْ إِن تَأْمَنْهُ بِقِنطَارٍ يُؤَدِّهِۦٓ إِلَيْكَ وَمِنْهُم مَّنْ إِن تَأْمَنْهُ بِدِينَارٍ لَّا يُؤَدِّهِۦٓ إِلَيْكَ إِلَّا مَا دُمْتَ عَلَيْهِ قَآئِمًا ۗ ذَٰلِكَ بِأَنَّهُمْ قَالُوا۟ لَيْسَ عَلَيْنَا فِى ٱلْأُمِّيِّـۧنَ سَبِيلٌ وَيَقُولُونَ عَلَى ٱللَّهِ ٱلْكَذِبَ وَهُمْ يَعْلَمُونَ

Transliteration wamin ahli l-kitābi man in tamanhu biqinṭārin yu-addihi ilayka wamin'hum man in tamanhu bidīnārin lā yu-addihi ilayka illā mā dum'ta ʿalayhi qāiman dhālika bi-annahum qālū laysa ʿalaynā fī l-umiyīna sabīlun wayaqūlūna ʿalā l-lahi l-kadhiba wahum yaʿlamūna

Yoruba Ó ń bẹ nínú àwọn onítírà, ẹni tí ó jẹ́ pé tí o bá fi ọkàn tán an pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ owó, ó máa dá a padà fún ọ. Ó sì ń bẹ nínú wọn, ẹni tí ó jẹ́ pé tí o bá fi ọkàn tán an pẹ̀lú owó dinar kan (owó kékeré), kò níí dá a padà fún ọ àyàfi tí o bá dógò tì í lọ́rùn. Ìyẹn nítorí pé wọ́n wí pé: “Wọn kò lè fí ọ̀nà kan kan bá wa wí nítorí àwọn aláìmọ̀ọ́nkọmọ̀ọ́nkà.” Ńṣe ni wọ́n ń pa irọ́ mọ́ Allāhu, wọ́n sì mọ̀.

Verse 76

بَلَىٰ مَنْ أَوْفَىٰ بِعَهْدِهِۦ وَٱتَّقَىٰ فَإِنَّ ٱللَّهَ يُحِبُّ ٱلْمُتَّقِينَ

Transliteration balā man awfā biʿahdihi wa-ittaqā fa-inna l-laha yuḥibbu l-mutaqīna

Yoruba Rárá (A máa bá wọn wí). Ẹnikẹ́ni tí ó bá mú àdéhùn rẹ̀ ṣẹ, tí ó sì bẹ̀rù (Allāhu), dájúdájú Allāhu nífẹ̀ẹ́ àwọn olùbẹ̀rù (Rẹ̀).

Verse 77

إِنَّ ٱلَّذِينَ يَشْتَرُونَ بِعَهْدِ ٱللَّهِ وَأَيْمَـٰنِهِمْ ثَمَنًا قَلِيلًا أُو۟لَـٰٓئِكَ لَا خَلَـٰقَ لَهُمْ فِى ٱلْـَٔاخِرَةِ وَلَا يُكَلِّمُهُمُ ٱللَّهُ وَلَا يَنظُرُ إِلَيْهِمْ يَوْمَ ٱلْقِيَـٰمَةِ وَلَا يُزَكِّيهِمْ وَلَهُمْ عَذَابٌ أَلِيمٌ

Transliteration inna alladhīna yashtarūna biʿahdi l-lahi wa-aymānihim thamanan qalīlan ulāika lā khalāqa lahum fī l-ākhirati walā yukallimuhumu l-lahu walā yanẓuru ilayhim yawma l-qiyāmati walā yuzakkīhim walahum ʿadhābun alīmun

Yoruba Dájúdájú àwọn tó ń ta májẹ̀mu Allāhu àti ìbúra wọn ní owó kékeré, àwọn wọ̀nyẹn, kò níí sí ìpín oore kan fún wọn ní Ọjọ́ Ìkẹ́yìn. Allāhu kò níí bá wọn sọ̀rọ̀, kò sì níí ṣíjú wò wọ́n ní Ọjọ́ Àjíǹde.Kò sì níí fọ̀ wọ́n mọ́ (nínú ẹ̀ṣẹ̀) Ìyà ẹlẹ́ta-eléro sì ń bẹ fún wọn.

Verse 78

وَإِنَّ مِنْهُمْ لَفَرِيقًا يَلْوُۥنَ أَلْسِنَتَهُم بِٱلْكِتَـٰبِ لِتَحْسَبُوهُ مِنَ ٱلْكِتَـٰبِ وَمَا هُوَ مِنَ ٱلْكِتَـٰبِ وَيَقُولُونَ هُوَ مِنْ عِندِ ٱللَّهِ وَمَا هُوَ مِنْ عِندِ ٱللَّهِ وَيَقُولُونَ عَلَى ٱللَّهِ ٱلْكَذِبَ وَهُمْ يَعْلَمُونَ

Transliteration wa-inna min'hum lafarīqan yalwūna alsinatahum bil-kitābi litaḥsabūhu mina l-kitābi wamā huwa mina l-kitābi wayaqūlūna huwa min ʿindi l-lahi wamā huwa min ʿindi l-lahi wayaqūlūna ʿalā l-lahi l-kadhiba wahum yaʿlamūna

Yoruba Dájúdájú ìjọ kan ń bẹ nínú wọn tó ń fi ahọ́n wọn yí tírà (Allāhu) padà, nítorí kí ẹ lè lérò pé lára tírà ló wà, kò sì sí lára tírà. Wọ́n sì ń wí pé: “Ó wá láti ọ̀dọ̀ Allāhu.” Kò sì wá láti ọ̀dọ̀ Allāhu. Wọ́n ń parọ́ mọ́ Allāhu, wọ́n sì mọ̀.

Verse 79

مَا كَانَ لِبَشَرٍ أَن يُؤْتِيَهُ ٱللَّهُ ٱلْكِتَـٰبَ وَٱلْحُكْمَ وَٱلنُّبُوَّةَ ثُمَّ يَقُولَ لِلنَّاسِ كُونُوا۟ عِبَادًا لِّى مِن دُونِ ٱللَّهِ وَلَـٰكِن كُونُوا۟ رَبَّـٰنِيِّـۧنَ بِمَا كُنتُمْ تُعَلِّمُونَ ٱلْكِتَـٰبَ وَبِمَا كُنتُمْ تَدْرُسُونَ

Transliteration mā kāna libasharin an yu'tiyahu l-lahu l-kitāba wal-ḥuk'ma wal-nubuwata thumma yaqūla lilnnāsi kūnū ʿibādan lī min dūni l-lahi walākin kūnū rabbāniyyīna bimā kuntum tuʿallimūna l-kitāba wabimā kuntum tadrusūna

Yoruba Kò lẹ́tọ̀ọ́ fún abara kan nígbà tí Allāhu bá fún un ní tírà, òye ìjìnlẹ̀ àti ipò Ànábì, lẹ́yìn náà kí ó máa sọ fún àwọn ènìyàn pé, “ẹ jẹ́ ẹrúsìn fún mi lẹ́yìn Allāhu.” Ṣùgbọ́n (ó máa sọ pé) “ẹ jẹ́ olùjọ́sìn fún Olúwa (kí ẹ sì máa fi ẹ̀kọ́ Rẹ̀ kọ́ àwọn ènìyàn) nítorí pé ẹ jẹ́ ẹni tí ń kọ́ àwọn ènìyàn ní tírà àti nítorí pé ẹ jẹ́ ẹni tí ń kọ́ ẹ̀kọ́ (nípa ẹ̀sìn).”

Verse 80

وَلَا يَأْمُرَكُمْ أَن تَتَّخِذُوا۟ ٱلْمَلَـٰٓئِكَةَ وَٱلنَّبِيِّـۧنَ أَرْبَابًا ۗ أَيَأْمُرُكُم بِٱلْكُفْرِ بَعْدَ إِذْ أَنتُم مُّسْلِمُونَ

Transliteration walā yamurakum an tattakhidhū l-malāikata wal-nabiyīna arbāban ayamurukum bil-kuf'ri baʿda idh antum mus'limūna

Yoruba (Ànábì kan) kò sì níí pa yín ní àṣẹ pé kí ẹ sọ àwọn mọlāika àti àwọn Ànábì di olúwa. Ṣé ó máa pa yín ní àṣẹ ṣíṣe àìgbàgbọ́ lẹ́yìn tí ẹ ti jẹ́ mùsùlùmí ni?

Verse 81

وَإِذْ أَخَذَ ٱللَّهُ مِيثَـٰقَ ٱلنَّبِيِّـۧنَ لَمَآ ءَاتَيْتُكُم مِّن كِتَـٰبٍ وَحِكْمَةٍ ثُمَّ جَآءَكُمْ رَسُولٌ مُّصَدِّقٌ لِّمَا مَعَكُمْ لَتُؤْمِنُنَّ بِهِۦ وَلَتَنصُرُنَّهُۥ ۚ قَالَ ءَأَقْرَرْتُمْ وَأَخَذْتُمْ عَلَىٰ ذَٰلِكُمْ إِصْرِى ۖ قَالُوٓا۟ أَقْرَرْنَا ۚ قَالَ فَٱشْهَدُوا۟ وَأَنَا۠ مَعَكُم مِّنَ ٱلشَّـٰهِدِينَ

Transliteration wa-idh akhadha l-lahu mīthāqa l-nabiyīna lamā ātaytukum min kitābin waḥik'matin thumma jāakum rasūlun muṣaddiqun limā maʿakum latu'minunna bihi walatanṣurunnahu qāla a-aqrartum wa-akhadhtum ʿalā dhālikum iṣ'rī qālū aqrarnā qāla fa-ish'hadū wa-anā maʿakum mina l-shāhidīna

Yoruba (Ẹ rántí) nígbà tí Allāhu gba àdéhùn lọ́wọ́ àwọn Ànábìpé: “Bí ó tilẹ̀ wù kí ó rí nígbà tí Mo bá fún yín ní tírà àti òye ìjìnlẹ́, lẹ́yìn náà Òjíṣẹ́ kan (ìyẹn, Ànábì Muhammad - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - yóò dé ba yín; ó máa fi èyí tó jẹ́ òdodo rinlẹ̀ nípa èyí tó wà pẹ̀lú yín, ẹ gbọ́dọ̀ gbà á gbọ́, ẹ sì gbọ́dọ̀ ràn án lọ́wọ́.” (Allāhu) sọ pé: “Ǹjẹ́ ẹ gbà? Ṣé ẹ sì máa lo àdéhùn Mi yìí?” Wọ́n sọ pé: “A gbà.” (Allāhu) sọ pé: “Nítorí náà, ẹ jẹ́rìí sí (àdéhùn náà). Èmi ń bẹ pẹ̀lú yín nínú àwọn Olùjẹ́rìí.”

Verse 82

فَمَن تَوَلَّىٰ بَعْدَ ذَٰلِكَ فَأُو۟لَـٰٓئِكَ هُمُ ٱلْفَـٰسِقُونَ

Transliteration faman tawallā baʿda dhālika fa-ulāika humu l-fāsiqūna

Yoruba Nítorí náà, ẹni tí ó bá kẹ̀yìn sí (Ànábì Muhammad - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -) lẹ́yìn (àdéhùn) yẹn, àwọn wọ̀nyẹn ni òbìlẹ̀jẹ́.

Verse 83

أَفَغَيْرَ دِينِ ٱللَّهِ يَبْغُونَ وَلَهُۥٓ أَسْلَمَ مَن فِى ٱلسَّمَـٰوَٰتِ وَٱلْأَرْضِ طَوْعًا وَكَرْهًا وَإِلَيْهِ يُرْجَعُونَ

Transliteration afaghayra dīni l-lahi yabghūna walahu aslama man fī l-samāwāti wal-arḍi ṭawʿan wakarhan wa-ilayhi yur'jaʿūna

Yoruba Ṣé ẹ̀sìn mìíràn yàtọ̀ sí ẹ̀sìn Allāhu ni wọ́n ń wá ni? Nígbà tí ó jẹ́ pé tiRẹ̀ ni gbogbo ẹni tí ń bẹ nínú àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ juwọ́ jusẹ̀ sílẹ̀ fún, wọ́n fẹ́ wọ́n kọ̀. Ọ̀dọ̀ Rẹ̀ sì ni Wọ́n máa dá wọn padà sí.

Verse 84

قُلْ ءَامَنَّا بِٱللَّهِ وَمَآ أُنزِلَ عَلَيْنَا وَمَآ أُنزِلَ عَلَىٰٓ إِبْرَٰهِيمَ وَإِسْمَـٰعِيلَ وَإِسْحَـٰقَ وَيَعْقُوبَ وَٱلْأَسْبَاطِ وَمَآ أُوتِىَ مُوسَىٰ وَعِيسَىٰ وَٱلنَّبِيُّونَ مِن رَّبِّهِمْ لَا نُفَرِّقُ بَيْنَ أَحَدٍ مِّنْهُمْ وَنَحْنُ لَهُۥ مُسْلِمُونَ

Transliteration qul āmannā bil-lahi wamā unzila ʿalaynā wamā unzila ʿalā ib'rāhīma wa-is'māʿīla wa-is'ḥāqa wayaʿqūba wal-asbāṭi wamā ūtiya mūsā waʿīsā wal-nabiyūna min rabbihim lā nufarriqu bayna aḥadin min'hum wanaḥnu lahu mus'limūna

Yoruba Sọ pé: “A gbàgbọ́ nínú Allāhu àti ohun tí wọ́n sọ̀kalẹ̀ fún wa àti ohun tí wọ́n sọ̀kalẹ̀ fún (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm, ’Ismọ̄‘īl, ’Ishāƙ, Ya‘ƙūb, àti àwọn àrọ́mọdọ́mọ (rẹ̀. A gbàgbọ́ nínú) ohun tí wọ́n fún (Ànábì) Mūsā àti ‘Īsā àti àwọn Ànábì láti ọ̀dọ̀ Olúwa wọn; A kò ya ẹnì kan kan sọ́tọ̀ nínú wọn. Àwa sì ni mùsùlùmí (olùjuwọ́-jusẹ̀-sílẹ̀) fún Un.”

Verse 85

وَمَن يَبْتَغِ غَيْرَ ٱلْإِسْلَـٰمِ دِينًا فَلَن يُقْبَلَ مِنْهُ وَهُوَ فِى ٱلْـَٔاخِرَةِ مِنَ ٱلْخَـٰسِرِينَ

Transliteration waman yabtaghi ghayra l-is'lāmi dīnan falan yuq'bala min'hu wahuwa fī l-ākhirati mina l-khāsirīna

Yoruba Ẹnikẹ́ni tí ó bá wá ẹ̀sìn kan ṣe yàtọ̀ sí ’Islām, A ò níí gbà á lọ́wọ́ rẹ̀. Ní Ọjọ́ Ìkẹ́yìn, ó sì máa wà nínú àwọn ẹni òfò.

Verse 86

كَيْفَ يَهْدِى ٱللَّهُ قَوْمًا كَفَرُوا۟ بَعْدَ إِيمَـٰنِهِمْ وَشَهِدُوٓا۟ أَنَّ ٱلرَّسُولَ حَقٌّ وَجَآءَهُمُ ٱلْبَيِّنَـٰتُ ۚ وَٱللَّهُ لَا يَهْدِى ٱلْقَوْمَ ٱلظَّـٰلِمِينَ

Transliteration kayfa yahdī l-lahu qawman kafarū baʿda īmānihim washahidū anna l-rasūla ḥaqqun wajāahumu l-bayinātu wal-lahu lā yahdī l-qawma l-ẓālimīna

Yoruba Báwo ni Allāhu yó ṣe fi ọ̀nà mọ ìjọ kan tó ṣàì gbàgbọ́ lẹ́yìn ìgbàgbọ́ wọn? Wọ́n sì jẹ́rìí pé dájúdájú Òjíṣẹ́ náà, òdodo ni. Àwọn ẹ̀rí tó yanjú sì ti dé bá wọn. Allāhu kì í fi ọ̀nà mọ ìjọ alábòsí.

Verse 87

أُو۟لَـٰٓئِكَ جَزَآؤُهُمْ أَنَّ عَلَيْهِمْ لَعْنَةَ ٱللَّهِ وَٱلْمَلَـٰٓئِكَةِ وَٱلنَّاسِ أَجْمَعِينَ

Transliteration ulāika jazāuhum anna ʿalayhim laʿnata l-lahi wal-malāikati wal-nāsi ajmaʿīna

Yoruba Àwọn wọ̀nyẹn, ẹ̀san wọn ni pé, dájúdájú ègún Allāhu àti (ègún) àwọn mọlāika àti (ègún) gbogbo àwọn ènìyàn ń bẹ lórí wọn.

Verse 88

خَـٰلِدِينَ فِيهَا لَا يُخَفَّفُ عَنْهُمُ ٱلْعَذَابُ وَلَا هُمْ يُنظَرُونَ

Transliteration khālidīna fīhā lā yukhaffafu ʿanhumu l-ʿadhābu walā hum yunẓarūna

Yoruba Olùṣegbére ni wọ́n nínú ègún. Nítorí náà, A ò níí ṣe ìyà náà ní fífúyẹ́ fún wọn, A ò sì níí fún wọn ní ìsinmi (nínú Iná).

Verse 89

إِلَّا ٱلَّذِينَ تَابُوا۟ مِنۢ بَعْدِ ذَٰلِكَ وَأَصْلَحُوا۟ فَإِنَّ ٱللَّهَ غَفُورٌ رَّحِيمٌ

Transliteration illā alladhīna tābū min baʿdi dhālika wa-aṣlaḥū fa-inna l-laha ghafūrun raḥīmun

Yoruba Àyàfi àwọn tó ronú pìwàdà lẹ́yìn ìyẹn, tí wọ́n sì ṣe àtúnṣe, nítorí pé dájúdájú Allāhu ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.

Verse 90

إِنَّ ٱلَّذِينَ كَفَرُوا۟ بَعْدَ إِيمَـٰنِهِمْ ثُمَّ ٱزْدَادُوا۟ كُفْرًا لَّن تُقْبَلَ تَوْبَتُهُمْ وَأُو۟لَـٰٓئِكَ هُمُ ٱلضَّآلُّونَ

Transliteration inna alladhīna kafarū baʿda īmānihim thumma iz'dādū kuf'ran lan tuq'bala tawbatuhum wa-ulāika humu l-ḍālūna

Yoruba Dájúdájú àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ lẹ́yìn ìgbàgbọ́ wọn, lẹ́yìn náà, wọ́n lékún ní àìgbàgbọ́, A ò níí gba ìronúpìwàdà wọn. Àwọn wọ̀nyẹn, àwọn ni olùṣìnà.

Verse 91

إِنَّ ٱلَّذِينَ كَفَرُوا۟ وَمَاتُوا۟ وَهُمْ كُفَّارٌ فَلَن يُقْبَلَ مِنْ أَحَدِهِم مِّلْءُ ٱلْأَرْضِ ذَهَبًا وَلَوِ ٱفْتَدَىٰ بِهِۦٓ ۗ أُو۟لَـٰٓئِكَ لَهُمْ عَذَابٌ أَلِيمٌ وَمَا لَهُم مِّن نَّـٰصِرِينَ

Transliteration inna alladhīna kafarū wamātū wahum kuffārun falan yuq'bala min aḥadihim mil'u l-arḍi dhahaban walawi if'tadā bihi ulāika lahum ʿadhābun alīmun wamā lahum min nāṣirīna

Yoruba Dájúdájú àwọn tó ṣàì gbàgbọ́, tí wọ́n sì kú nígbà tí wọ́n jẹ́ aláìgbàgbọ́, A ò níí gba ẹ̀kún ilẹ̀ wúrà lọ́wọ́ ẹnikẹ́ni nínú wọn, ìbáà fi ṣèràpadà (fún ẹ̀mí ara rẹ̀ níbi Iná). Àwọn wọ̀nyẹn ni ìyà ẹlẹ́ta-eléro ń bẹ fún. Kò sì níí sí àwọn olùrànlọ́wọ́ fún wọn.

Verse 92

لَن تَنَالُوا۟ ٱلْبِرَّ حَتَّىٰ تُنفِقُوا۟ مِمَّا تُحِبُّونَ ۚ وَمَا تُنفِقُوا۟ مِن شَىْءٍ فَإِنَّ ٱللَّهَ بِهِۦ عَلِيمٌ

Transliteration lan tanālū l-bira ḥattā tunfiqū mimmā tuḥibbūna wamā tunfiqū min shayin fa-inna l-laha bihi ʿalīmun

Yoruba Ọwọ́ yin kò lè ba oore àyàfi tí ẹ bá ń ná nínú ohun tí ẹ nífẹ̀ẹ́ sí. Àti pé ohunkóhun tí ẹ bá ná, dájúdájú Allāhu ni Onímọ̀ nípa rẹ̀.

Verse 93

۞ كُلُّ ٱلطَّعَامِ كَانَ حِلًّا لِّبَنِىٓ إِسْرَٰٓءِيلَ إِلَّا مَا حَرَّمَ إِسْرَٰٓءِيلُ عَلَىٰ نَفْسِهِۦ مِن قَبْلِ أَن تُنَزَّلَ ٱلتَّوْرَىٰةُ ۗ قُلْ فَأْتُوا۟ بِٱلتَّوْرَىٰةِ فَٱتْلُوهَآ إِن كُنتُمْ صَـٰدِقِينَ

Transliteration kullu l-ṭaʿāmi kāna ḥillan libanī is'rāīla illā mā ḥarrama is'rāīlu ʿalā nafsihi min qabli an tunazzala l-tawrātu qul fatū bil-tawrāti fa-it'lūhā in kuntum ṣādiqīna

Yoruba Gbogbo oúnjẹ ló jẹ́ ẹ̀tọ́ fún àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl àyàfi èyí tí ’Isrọ̄’īl bá ṣe ní èèwọ̀ fún ẹ̀mí ara rẹ̀ ṣíwájú kí A tó sọ at-Taorāh kalẹ̀. Sọ pé: “Nítorí náà, ẹ mú at-Taorāh wá, kí ẹ sì kà á síta tí ẹ̀yin bá jẹ́ olódodo.”

Verse 94

فَمَنِ ٱفْتَرَىٰ عَلَى ٱللَّهِ ٱلْكَذِبَ مِنۢ بَعْدِ ذَٰلِكَ فَأُو۟لَـٰٓئِكَ هُمُ ٱلظَّـٰلِمُونَ

Transliteration famani if'tarā ʿalā l-lahi l-kadhiba min baʿdi dhālika fa-ulāika humu l-ẓālimūna

Yoruba Nítorí náà, ẹnikẹ́ni tí ó bá dá àdápa irọ́ mọ́ Allāhu lẹ́yìn ìyẹn, àwọn wọ̀nyẹn, àwọn ni alábòsí.

Verse 95

قُلْ صَدَقَ ٱللَّهُ ۗ فَٱتَّبِعُوا۟ مِلَّةَ إِبْرَٰهِيمَ حَنِيفًا وَمَا كَانَ مِنَ ٱلْمُشْرِكِينَ

Transliteration qul ṣadaqa l-lahu fa-ittabiʿū millata ib'rāhīma ḥanīfan wamā kāna mina l-mush'rikīna

Yoruba Sọ pé: “Allāhu sọ òdodo. Nítorí náà, ẹ tẹ̀lé ẹ̀sìn (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm, olùdúró-déédé-nínú-’Islām. Kò sì sí nínú àwọn ọ̀ṣẹbọ.”

Verse 96

إِنَّ أَوَّلَ بَيْتٍ وُضِعَ لِلنَّاسِ لَلَّذِى بِبَكَّةَ مُبَارَكًا وَهُدًى لِّلْعَـٰلَمِينَ

Transliteration inna awwala baytin wuḍiʿa lilnnāsi lalladhī bibakkata mubārakan wahudan lil'ʿālamīna

Yoruba Dájúdájú ilé àkọ́kọ́ tí A fi lélẹ̀ fún àwọn ènìyàn ni èyí tí ó wà ní Bakkah.(Ó jẹ́ ilé) ìbùkún àti ìmọ̀nà fún gbogbo ẹ̀dá.

Verse 97

فِيهِ ءَايَـٰتٌۢ بَيِّنَـٰتٌ مَّقَامُ إِبْرَٰهِيمَ ۖ وَمَن دَخَلَهُۥ كَانَ ءَامِنًا ۗ وَلِلَّهِ عَلَى ٱلنَّاسِ حِجُّ ٱلْبَيْتِ مَنِ ٱسْتَطَاعَ إِلَيْهِ سَبِيلًا ۚ وَمَن كَفَرَ فَإِنَّ ٱللَّهَ غَنِىٌّ عَنِ ٱلْعَـٰلَمِينَ

Transliteration fīhi āyātun bayyinātun maqāmu ib'rāhīma waman dakhalahu kāna āminan walillahi ʿalā l-nāsi ḥijju l-bayti mani is'taṭāʿa ilayhi sabīlan waman kafara fa-inna l-laha ghaniyyun ʿani l-ʿālamīna

Yoruba Àwọn àmì tó yanjú wà nínú rẹ̀; ibùdúró (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm. Ẹnikẹ́ni tí ó bá wọ inú rẹ̀ ti di ẹni ìfàyàbalẹ̀. Allāhu ṣe àbẹ̀wò sí Ilé náà ní dandan fún àwọn ènìyàn, tó lágbára ọ̀nà tí ó máa gbà débẹ̀. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì ṣàì gbàgbọ́, dájúdájú Allāhu ni Ọlọ́rọ̀ tí kò bùkátà sí gbogbo ẹ̀dá.

Verse 98

قُلْ يَـٰٓأَهْلَ ٱلْكِتَـٰبِ لِمَ تَكْفُرُونَ بِـَٔايَـٰتِ ٱللَّهِ وَٱللَّهُ شَهِيدٌ عَلَىٰ مَا تَعْمَلُونَ

Transliteration qul yāahla l-kitābi lima takfurūna biāyāti l-lahi wal-lahu shahīdun ʿalā mā taʿmalūna

Yoruba Sọ pé: “Ẹ̀yin onítírà, nítorí kí ni ẹ óò fi ṣàì gbàgbọ́ nínú àwọn āyah Allāhu? Allāhu sì ni Arínú-róde ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.”

Verse 99

قُلْ يَـٰٓأَهْلَ ٱلْكِتَـٰبِ لِمَ تَصُدُّونَ عَن سَبِيلِ ٱللَّهِ مَنْ ءَامَنَ تَبْغُونَهَا عِوَجًا وَأَنتُمْ شُهَدَآءُ ۗ وَمَا ٱللَّهُ بِغَـٰفِلٍ عَمَّا تَعْمَلُونَ

Transliteration qul yāahla l-kitābi lima taṣuddūna ʿan sabīli l-lahi man āmana tabghūnahā ʿiwajan wa-antum shuhadāu wamā l-lahu bighāfilin ʿammā taʿmalūna

Yoruba Sọ pé: “Ẹ̀yin onítírà, nítorí kí ni ẹ fi ń ṣẹ́rí ẹni tó gbàgbọ́ lódodo kúrò lójú ọ̀nà (ẹ̀sìn) Allāhu, tí ẹ̀ ń fẹ́ kí ó wọ́,ẹ sì jẹ́rìí (sí òdodo ’Islām)? Allāhu kì í ṣe Onígbàgbé nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.”

Verse 100

يَـٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُوٓا۟ إِن تُطِيعُوا۟ فَرِيقًا مِّنَ ٱلَّذِينَ أُوتُوا۟ ٱلْكِتَـٰبَ يَرُدُّوكُم بَعْدَ إِيمَـٰنِكُمْ كَـٰفِرِينَ

Transliteration yāayyuhā alladhīna āmanū in tuṭīʿū farīqan mina alladhīna ūtū l-kitāba yaruddūkum baʿda īmānikum kāfirīna

Yoruba Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, tí ẹ bá tẹ̀lé apá kan nínú àwọn tí A fún ní tírà, wọ́n máa da yín padà lẹ́yìn ìgbàgbọ́ òdodo yín sí ipò aláìgbàgbọ́.

Verse 101

وَكَيْفَ تَكْفُرُونَ وَأَنتُمْ تُتْلَىٰ عَلَيْكُمْ ءَايَـٰتُ ٱللَّهِ وَفِيكُمْ رَسُولُهُۥ ۗ وَمَن يَعْتَصِم بِٱللَّهِ فَقَدْ هُدِىَ إِلَىٰ صِرَٰطٍ مُّسْتَقِيمٍ

Transliteration wakayfa takfurūna wa-antum tut'lā ʿalaykum āyātu l-lahi wafīkum rasūluhu waman yaʿtaṣim bil-lahi faqad hudiya ilā ṣirāṭin mus'taqīmin

Yoruba Báwo ni ẹ̀yin ṣe lè ṣàì gbàgbọ́, ẹ̀yin mà ni wọ́n ń ké àwọn āyah Allāhu fún, Òjíṣẹ́ Rẹ̀ sì wà láààrin yín! Ẹnikẹ́ni tí ó bá dúró ṣinṣin ti Allāhu, A ti tọ́ ọ sí ọ̀nà tààrà.1

Verse 102

يَـٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُوا۟ ٱتَّقُوا۟ ٱللَّهَ حَقَّ تُقَاتِهِۦ وَلَا تَمُوتُنَّ إِلَّا وَأَنتُم مُّسْلِمُونَ

Transliteration yāayyuhā alladhīna āmanū ittaqū l-laha ḥaqqa tuqātihi walā tamūtunna illā wa-antum mus'limūna

Yoruba Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ bẹ̀rù Allāhu bí ó ṣe tọ́ láti bẹ̀rù Rẹ̀. Ẹ̀yin kò sì gbọdọ̀ kú àyàfi kí ẹ wà ní ipò mùsùlùmí.

Verse 103

وَٱعْتَصِمُوا۟ بِحَبْلِ ٱللَّهِ جَمِيعًا وَلَا تَفَرَّقُوا۟ ۚ وَٱذْكُرُوا۟ نِعْمَتَ ٱللَّهِ عَلَيْكُمْ إِذْ كُنتُمْ أَعْدَآءً فَأَلَّفَ بَيْنَ قُلُوبِكُمْ فَأَصْبَحْتُم بِنِعْمَتِهِۦٓ إِخْوَٰنًا وَكُنتُمْ عَلَىٰ شَفَا حُفْرَةٍ مِّنَ ٱلنَّارِ فَأَنقَذَكُم مِّنْهَا ۗ كَذَٰلِكَ يُبَيِّنُ ٱللَّهُ لَكُمْ ءَايَـٰتِهِۦ لَعَلَّكُمْ تَهْتَدُونَ

Transliteration wa-iʿ'taṣimū biḥabli l-lahi jamīʿan walā tafarraqū wa-udh'kurū niʿ'mata l-lahi ʿalaykum idh kuntum aʿdāan fa-allafa bayna qulūbikum fa-aṣbaḥtum biniʿ'matihi ikh'wānan wakuntum ʿalā shafā ḥuf'ratin mina l-nāri fa-anqadhakum min'hā kadhālika yubayyinu l-lahu lakum āyātihi laʿallakum tahtadūna

Yoruba Ẹ dìmọ́ okùn Allāhu (al-Ƙur’ān) ní àpapọ̀, ẹ má ṣe pín sí ìjọ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Kí ẹ sì rántí ìkẹ́ Allāhu tí ń bẹ lórí yín (pé) nígbà tí ẹ jẹ́ ọ̀tá (ara yín nígbà àìmọ̀kan), Ó pa ọkàn yín pọ̀ mọ́ra wọn (pẹ̀lú ’Islām), ẹ sì di ọmọ ìyá pẹ̀lú ìkẹ́ Rẹ̀; àti (nígbà tí) ẹ wà létí ọ̀gbun Iná, Ó gbà yín là kúrò nínú rẹ̀. Báyẹn ni Allāhu ṣe ń ṣe àlàyé àwọn āyah Rẹ̀ fún yín nítorí kí ẹ lè mọ̀nà (’Islām).

Verse 104

وَلْتَكُن مِّنكُمْ أُمَّةٌ يَدْعُونَ إِلَى ٱلْخَيْرِ وَيَأْمُرُونَ بِٱلْمَعْرُوفِ وَيَنْهَوْنَ عَنِ ٱلْمُنكَرِ ۚ وَأُو۟لَـٰٓئِكَ هُمُ ٱلْمُفْلِحُونَ

Transliteration waltakun minkum ummatun yadʿūna ilā l-khayri wayamurūna bil-maʿrūfi wayanhawna ʿani l-munkari wa-ulāika humu l-muf'liḥūna

Yoruba Kí ó máa bẹ nínú yín, ìjọ kan tí yóò máa pèpè síbi ohun tó lóore, wọn yóò máa pàṣẹ ohun rere, wọn yó sì máa kọ ohun burúkú. Àwọn wọ̀nyẹn, àwọn sì ni olùjèrè.

Verse 105

وَلَا تَكُونُوا۟ كَٱلَّذِينَ تَفَرَّقُوا۟ وَٱخْتَلَفُوا۟ مِنۢ بَعْدِ مَا جَآءَهُمُ ٱلْبَيِّنَـٰتُ ۚ وَأُو۟لَـٰٓئِكَ لَهُمْ عَذَابٌ عَظِيمٌ

Transliteration walā takūnū ka-alladhīna tafarraqū wa-ikh'talafū min baʿdi mā jāahumu l-bayinātu wa-ulāika lahum ʿadhābun ʿaẓīmun

Yoruba Ẹ má ṣe dà bí àwọn tó sọra wọn di ìjọ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, tí wọ́n sì yapa ẹnu (sí ’Islām) lẹ́yìn tí àwọn àlàyé tó yanjú ti dé bá wọn. Àwọn wọ̀nyẹn sì ni ìyà ńlá ń bẹ fún.

Verse 106

يَوْمَ تَبْيَضُّ وُجُوهٌ وَتَسْوَدُّ وُجُوهٌ ۚ فَأَمَّا ٱلَّذِينَ ٱسْوَدَّتْ وُجُوهُهُمْ أَكَفَرْتُم بَعْدَ إِيمَـٰنِكُمْ فَذُوقُوا۟ ٱلْعَذَابَ بِمَا كُنتُمْ تَكْفُرُونَ

Transliteration yawma tabyaḍḍu wujūhun wataswaddu wujūhun fa-ammā alladhīna is'waddat wujūhuhum akafartum baʿda īmānikum fadhūqū l-ʿadhāba bimā kuntum takfurūna

Yoruba Ní ọjọ́ tí àwọn ojú kan yóò funfun (ìmọ́lẹ̀). Àwọn ojú kan yó sì dúdú. Ní ti àwọn tí ojú wọn dúdú, (A ó bi wọ́n pé:) "Ṣé ẹ ṣàì gbàgbọ́ lẹ́yìn ìgbàgbọ́ yín ni?" Nítorí náà, ẹ tọ́ ìyà wò nítorí pé ẹ ṣàì gbàgbọ́.

Verse 107

وَأَمَّا ٱلَّذِينَ ٱبْيَضَّتْ وُجُوهُهُمْ فَفِى رَحْمَةِ ٱللَّهِ هُمْ فِيهَا خَـٰلِدُونَ

Transliteration wa-ammā alladhīna ib'yaḍḍat wujūhuhum fafī raḥmati l-lahi hum fīhā khālidūna

Yoruba Ní ti àwọn tí ojú wọn funfun (ìmọ́lẹ̀), nínú ìkẹ́ Allāhu ni wọn yóò wà. Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀.

Verse 108

تِلْكَ ءَايَـٰتُ ٱللَّهِ نَتْلُوهَا عَلَيْكَ بِٱلْحَقِّ ۗ وَمَا ٱللَّهُ يُرِيدُ ظُلْمًا لِّلْعَـٰلَمِينَ

Transliteration til'ka āyātu l-lahi natlūhā ʿalayka bil-ḥaqi wamā l-lahu yurīdu ẓul'man lil'ʿālamīna

Yoruba Ìwọ̀nyí ni àwọn āyah Allāhu, tí À ń ké e fún ọ pẹ̀lú òdodo. Allāhu kò sì gbèrò àbòsí kan sí gbogbo ẹ̀dá.

Verse 109

وَلِلَّهِ مَا فِى ٱلسَّمَـٰوَٰتِ وَمَا فِى ٱلْأَرْضِ ۚ وَإِلَى ٱللَّهِ تُرْجَعُ ٱلْأُمُورُ

Transliteration walillahi mā fī l-samāwāti wamā fī l-arḍi wa-ilā l-lahi tur'jaʿu l-umūru

Yoruba Ti Allāhu ni ohunkóhun tó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ohunkóhun tó wà nínú ilẹ̀. Ọ̀dọ̀ Allāhu sì ni wọ́n máa ṣẹ́rí àwọn ọ̀rọ̀ ẹ̀dá padà sí.

Verse 110

كُنتُمْ خَيْرَ أُمَّةٍ أُخْرِجَتْ لِلنَّاسِ تَأْمُرُونَ بِٱلْمَعْرُوفِ وَتَنْهَوْنَ عَنِ ٱلْمُنكَرِ وَتُؤْمِنُونَ بِٱللَّهِ ۗ وَلَوْ ءَامَنَ أَهْلُ ٱلْكِتَـٰبِ لَكَانَ خَيْرًا لَّهُم ۚ مِّنْهُمُ ٱلْمُؤْمِنُونَ وَأَكْثَرُهُمُ ٱلْفَـٰسِقُونَ

Transliteration kuntum khayra ummatin ukh'rijat lilnnāsi tamurūna bil-maʿrūfi watanhawna ʿani l-munkari watu'minūna bil-lahi walaw āmana ahlu l-kitābi lakāna khayran lahum min'humu l-mu'minūna wa-aktharuhumu l-fāsiqūna

Yoruba Ẹ jẹ́ ìjọ tó lóore jùlọ, tí A gbé dìde fún àwọn ènìyàn; ẹ̀ ń pàṣẹ ohun rere, ẹ̀ ń kọ ohun burúkú, ẹ sì gbàgbọ́ nínú Allāhu. Tí ó bá jẹ́ pé àwọn ahlul-kitāb gbàgbọ́ lódodo ni, ìbá lóore jùlọ fún wọn. Onígbàgbọ́ òdodo wà nínú wọn,ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn sì ni òbìlẹ̀jẹ́.

Verse 111

لَن يَضُرُّوكُمْ إِلَّآ أَذًى ۖ وَإِن يُقَـٰتِلُوكُمْ يُوَلُّوكُمُ ٱلْأَدْبَارَ ثُمَّ لَا يُنصَرُونَ

Transliteration lan yaḍurrūkum illā adhan wa-in yuqātilūkum yuwallūkumu l-adbāra thumma lā yunṣarūna

Yoruba Wọn kò níí kó ìnira ba yín àyàfi ìpalára díẹ̀. Tí wọ́n bá sì ba yín jà, wọ́n á sá fún yín. Lẹ́yìn náà, A ò níí ràn wọ́n lọ́wọ́.

Verse 112

ضُرِبَتْ عَلَيْهِمُ ٱلذِّلَّةُ أَيْنَ مَا ثُقِفُوٓا۟ إِلَّا بِحَبْلٍ مِّنَ ٱللَّهِ وَحَبْلٍ مِّنَ ٱلنَّاسِ وَبَآءُو بِغَضَبٍ مِّنَ ٱللَّهِ وَضُرِبَتْ عَلَيْهِمُ ٱلْمَسْكَنَةُ ۚ ذَٰلِكَ بِأَنَّهُمْ كَانُوا۟ يَكْفُرُونَ بِـَٔايَـٰتِ ٱللَّهِ وَيَقْتُلُونَ ٱلْأَنۢبِيَآءَ بِغَيْرِ حَقٍّ ۚ ذَٰلِكَ بِمَا عَصَوا۟ وَّكَانُوا۟ يَعْتَدُونَ

Transliteration ḍuribat ʿalayhimu l-dhilatu ayna mā thuqifū illā biḥablin mina l-lahi waḥablin mina l-nāsi wabāū bighaḍabin mina l-lahi waḍuribat ʿalayhimu l-maskanatu dhālika bi-annahum kānū yakfurūna biāyāti l-lahi wayaqtulūna l-anbiyāa bighayri ḥaqqin dhālika bimā ʿaṣaw wakānū yaʿtadūna

Yoruba Àbùkù yóò máa bá wọn níbikíbi tí ọwọ́ àwọn (mùsùlùmí) bá ti bà wọ́n àfi (tí wọ́n bá ń bẹ) pẹ̀lú àdéhùn àti ààbò láti ọ̀dọ̀ Allāhu (ìyẹn ni pé, kí wọ́n gba ’Islām) àti àdéhùn àti ààbò láti ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn (ìyẹn ni pé, kí wọ́n gbà láti máa san owó ìsákọ́lẹ̀ fún ìjọba ’Islām). Wọ́n ṣẹ́rí padà pẹ̀lú ìbínú láti ọ̀dọ̀ Allāhu. Wọ́n sì kó òṣì bá wọn. Ìyẹn nítorí pé, dájúdájú wọ́n ṣàì gbàgbọ́ nínú àwọn āyah Allāhu, wọ́n tún ń pa àwọn Ànábì láì lẹ́tọ̀ọ́. Ìyẹn nítorí pé, wọ́n yapa (àṣẹ Allāhu), wọ́n sì ń tayọ ẹnu ààlà.

Verse 113

۞ لَيْسُوا۟ سَوَآءً ۗ مِّنْ أَهْلِ ٱلْكِتَـٰبِ أُمَّةٌ قَآئِمَةٌ يَتْلُونَ ءَايَـٰتِ ٱللَّهِ ءَانَآءَ ٱلَّيْلِ وَهُمْ يَسْجُدُونَ

Transliteration laysū sawāan min ahli l-kitābi ummatun qāimatun yatlūna āyāti l-lahi ānāa al-layli wahum yasjudūna

Yoruba (Àwọn onítírà) kò rí bákan náà. Ìjọ kan tó dúró déédé wà nínú àwọn onítírà, tí ń ké àwọn āyah Allāhu ní àkókò òru, tí wọ́n sì ń forí kanlẹ̀ (lórí ìrun).

Verse 114

يُؤْمِنُونَ بِٱللَّهِ وَٱلْيَوْمِ ٱلْـَٔاخِرِ وَيَأْمُرُونَ بِٱلْمَعْرُوفِ وَيَنْهَوْنَ عَنِ ٱلْمُنكَرِ وَيُسَـٰرِعُونَ فِى ٱلْخَيْرَٰتِ وَأُو۟لَـٰٓئِكَ مِنَ ٱلصَّـٰلِحِينَ

Transliteration yu'minūna bil-lahi wal-yawmi l-ākhiri wayamurūna bil-maʿrūfi wayanhawna ʿani l-munkari wayusāriʿūna fī l-khayrāti wa-ulāika mina l-ṣāliḥīna

Yoruba Wọ́n gbàgbọ́ nínú Allāhu àti Ọjọ́ Ìkẹ́yìn. Wọ́n ń pàṣẹ ohun rere, wọ́n ń kọ ohun burúkú, wọ́n sì ń yara níbi àwọn iṣẹ́ olóoore. Àwọn wọ̀nyẹn wà nínú àwọn ẹni rere.1

Verse 115

وَمَا يَفْعَلُوا۟ مِنْ خَيْرٍ فَلَن يُكْفَرُوهُ ۗ وَٱللَّهُ عَلِيمٌۢ بِٱلْمُتَّقِينَ

Transliteration wamā yafʿalū min khayrin falan yuk'farūhu wal-lahu ʿalīmun bil-mutaqīna

Yoruba Ohunkóhun tí wọ́n bá ń ṣe ní iṣẹ́ rere, A ò níí jẹ́ kí ẹ̀san rẹ̀ gbé. Allāhu sì ni Onímọ̀ nípa àwọn olùbẹ̀rù (Rẹ̀).

Verse 116

إِنَّ ٱلَّذِينَ كَفَرُوا۟ لَن تُغْنِىَ عَنْهُمْ أَمْوَٰلُهُمْ وَلَآ أَوْلَـٰدُهُم مِّنَ ٱللَّهِ شَيْـًٔا ۖ وَأُو۟لَـٰٓئِكَ أَصْحَـٰبُ ٱلنَّارِ ۚ هُمْ فِيهَا خَـٰلِدُونَ

Transliteration inna alladhīna kafarū lan tugh'niya ʿanhum amwāluhum walā awlāduhum mina l-lahi shayan wa-ulāika aṣḥābu l-nāri hum fīhā khālidūna

Yoruba Dájúdájú àwọn tó ṣàì gbàgbọ́, àwọn dúkìá wọn àti àwọn ọmọ wọn kò níí rọ̀ wọ́n lọ́rọ̀ kiní kan (níbi ìyà) lọ́dọ̀ Allāhu. Àwọn wọ̀nyẹn sì ni èrò inú Iná. Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀.

Verse 117

مَثَلُ مَا يُنفِقُونَ فِى هَـٰذِهِ ٱلْحَيَوٰةِ ٱلدُّنْيَا كَمَثَلِ رِيحٍ فِيهَا صِرٌّ أَصَابَتْ حَرْثَ قَوْمٍ ظَلَمُوٓا۟ أَنفُسَهُمْ فَأَهْلَكَتْهُ ۚ وَمَا ظَلَمَهُمُ ٱللَّهُ وَلَـٰكِنْ أَنفُسَهُمْ يَظْلِمُونَ

Transliteration mathalu mā yunfiqūna fī hādhihi l-ḥayati l-dun'yā kamathali rīḥin fīhā ṣirrun aṣābat ḥartha qawmin ẓalamū anfusahum fa-ahlakathu wamā ẓalamahumu l-lahu walākin anfusahum yaẓlimūna

Yoruba Àpèjúwe ohun tí wọ́n ń ná nínú ìṣẹ̀mí ayé yìí dà bí àpèjúwe afẹ́fẹ́ tí atẹ́gùn òtútù líle wà nínú rẹ̀. Ó fẹ́ lu oko àwọn ènìyàn tó ṣe àbòsí s’órí ara wọn. Ó sì pa á run. Allāhu kò sì ṣe àbòsí sí wọn, ṣùgbọ́n ẹ̀mí ara wọn ni wọ́n ń ṣàbòsí sí.

Verse 118

يَـٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُوا۟ لَا تَتَّخِذُوا۟ بِطَانَةً مِّن دُونِكُمْ لَا يَأْلُونَكُمْ خَبَالًا وَدُّوا۟ مَا عَنِتُّمْ قَدْ بَدَتِ ٱلْبَغْضَآءُ مِنْ أَفْوَٰهِهِمْ وَمَا تُخْفِى صُدُورُهُمْ أَكْبَرُ ۚ قَدْ بَيَّنَّا لَكُمُ ٱلْـَٔايَـٰتِ ۖ إِن كُنتُمْ تَعْقِلُونَ

Transliteration yāayyuhā alladhīna āmanū lā tattakhidhū biṭānatan min dūnikum lā yalūnakum khabālan waddū mā ʿanittum qad badati l-baghḍāu min afwāhihim wamā tukh'fī ṣudūruhum akbaru qad bayyannā lakumu l-āyāti in kuntum taʿqilūna

Yoruba Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ má ṣe mú ọ̀rẹ́ finúhannú kan yàtọ̀ sí ara yín. Wọn kò níí géwọ́ aburú kúrú fún yín. Wọ́n sì nífẹ̀ẹ́ sí ohun tí ó máa kó ìnira ba yín. Ìkórira kúkú ti fojú hàn láti ẹnu wọn. Ohun tí ó sì pamọ́ sínú ọkàn wọn tóbi jùlọ. A ti ṣàlàyé àwọn āyah fún yín, tí ẹ̀yin bá jẹ́ onílàákàyè.1

Verse 119

هَـٰٓأَنتُمْ أُو۟لَآءِ تُحِبُّونَهُمْ وَلَا يُحِبُّونَكُمْ وَتُؤْمِنُونَ بِٱلْكِتَـٰبِ كُلِّهِۦ وَإِذَا لَقُوكُمْ قَالُوٓا۟ ءَامَنَّا وَإِذَا خَلَوْا۟ عَضُّوا۟ عَلَيْكُمُ ٱلْأَنَامِلَ مِنَ ٱلْغَيْظِ ۚ قُلْ مُوتُوا۟ بِغَيْظِكُمْ ۗ إِنَّ ٱللَّهَ عَلِيمٌۢ بِذَاتِ ٱلصُّدُورِ

Transliteration hāantum ulāi tuḥibbūnahum walā yuḥibbūnakum watu'minūna bil-kitābi kullihi wa-idhā laqūkum qālū āmannā wa-idhā khalaw ʿaḍḍū ʿalaykumu l-anāmila mina l-ghayẓi qul mūtū bighayẓikum inna l-laha ʿalīmun bidhāti l-ṣudūri

Yoruba Kíyè sí i, ẹ̀yin wọ̀nyí nífẹ̀ẹ́ wọn, àwọn kò sì nífẹ̀ẹ́ yín. Ẹ̀yin gbàgbọ́ nínú gbogbo àwọn tírà pátápátá. Nígbà tí wọ́n bá sì pàdé yín, wọ́n á wí pé: “Àwa gbàgbọ́.” Nígbà tí ó bá sì ku àwọn nìkan, wọn yóò máa deyín mọ́ ìka lórí yín ní ti ìbínú. Sọ pé: “Ẹ kú pẹ̀lú ìbínú yín.” Dájúdájú Allāhu ni Onímọ̀ nípa ohun tí ń bẹ nínú àwọn igbá-àyà ẹ̀dá.

Verse 120

إِن تَمْسَسْكُمْ حَسَنَةٌ تَسُؤْهُمْ وَإِن تُصِبْكُمْ سَيِّئَةٌ يَفْرَحُوا۟ بِهَا ۖ وَإِن تَصْبِرُوا۟ وَتَتَّقُوا۟ لَا يَضُرُّكُمْ كَيْدُهُمْ شَيْـًٔا ۗ إِنَّ ٱللَّهَ بِمَا يَعْمَلُونَ مُحِيطٌ

Transliteration in tamsaskum ḥasanatun tasu'hum wa-in tuṣib'kum sayyi-atun yafraḥū bihā wa-in taṣbirū watattaqū lā yaḍurrukum kayduhum shayan inna l-laha bimā yaʿmalūna muḥīṭun

Yoruba Tí dáadáa kan bá kàn yín, ó máa kó ìbànújẹ́ bà wọn. Tí aburú kan bá sì ṣẹlẹ̀ si yín, wọ́n máa dunnú sí i. Tí ẹ̀yin bá ṣe sùúrù, tí ẹ sì ṣọ́ra (fún wọn), ète wọn kò níí kó ìnira kan kan ba yín. Dájúdájú Allāhu ni Alámọ̀tán nípa ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́.

Verse 121

وَإِذْ غَدَوْتَ مِنْ أَهْلِكَ تُبَوِّئُ ٱلْمُؤْمِنِينَ مَقَـٰعِدَ لِلْقِتَالِ ۗ وَٱللَّهُ سَمِيعٌ عَلِيمٌ

Transliteration wa-idh ghadawta min ahlika tubawwi-u l-mu'minīna maqāʿida lil'qitāli wal-lahu samīʿun ʿalīmun

Yoruba (Rántí) nígbà tí o jí kúrò lọ́dọ̀ àwọn ara ilé rẹ ní ìdájí kùtùkùtù, tí ò ń fi àwọn onígbàgbọ́ òdodo sí àyè ibùjagun, Allāhu ni Olùgbọ́, Onímọ̀.

Verse 122

إِذْ هَمَّت طَّآئِفَتَانِ مِنكُمْ أَن تَفْشَلَا وَٱللَّهُ وَلِيُّهُمَا ۗ وَعَلَى ٱللَّهِ فَلْيَتَوَكَّلِ ٱلْمُؤْمِنُونَ

Transliteration idh hammat ṭāifatāni minkum an tafshalā wal-lahu waliyyuhumā waʿalā l-lahi falyatawakkali l-mu'minūna

Yoruba (Rántí) nígbà tí ìjọ méjì nínú yín rò láti ṣojo. Allāhu sì ni Aláfẹ̀yìntì àwọn méjèèjì. Allāhu sì ni kí àwọn onígbàgbọ́ òdodo gbáralé.

Verse 123

وَلَقَدْ نَصَرَكُمُ ٱللَّهُ بِبَدْرٍ وَأَنتُمْ أَذِلَّةٌ ۖ فَٱتَّقُوا۟ ٱللَّهَ لَعَلَّكُمْ تَشْكُرُونَ

Transliteration walaqad naṣarakumu l-lahu bibadrin wa-antum adhillatun fa-ittaqū l-laha laʿallakum tashkurūna

Yoruba Allāhu kúkú fún yín ní ìṣẹ́gun ní ogun Badr, nígbà tí ẹ̀yin jẹ́ aláìlágbára. Nítorí náà, ẹ bẹ̀rù Allāhu kí ẹ lè dúpẹ́ (fún Un).

Verse 124

إِذْ تَقُولُ لِلْمُؤْمِنِينَ أَلَن يَكْفِيَكُمْ أَن يُمِدَّكُمْ رَبُّكُم بِثَلَـٰثَةِ ءَالَـٰفٍ مِّنَ ٱلْمَلَـٰٓئِكَةِ مُنزَلِينَ

Transliteration idh taqūlu lil'mu'minīna alan yakfiyakum an yumiddakum rabbukum bithalāthati ālāfin mina l-malāikati munzalīna

Yoruba Rántí nígbà tí ò ń sọ fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo pé: “Ṣé kò níí to yín tí Olúwa yín bá ṣe ìrànlọ́wọ́ fún yín pẹ̀lú ẹgbẹ̀rún mẹ́ta nínú àwọn mọlāika, tí Wọ́n máa sọ̀kalẹ̀?”

Verse 125

بَلَىٰٓ ۚ إِن تَصْبِرُوا۟ وَتَتَّقُوا۟ وَيَأْتُوكُم مِّن فَوْرِهِمْ هَـٰذَا يُمْدِدْكُمْ رَبُّكُم بِخَمْسَةِ ءَالَـٰفٍ مِّنَ ٱلْمَلَـٰٓئِكَةِ مُسَوِّمِينَ

Transliteration balā in taṣbirū watattaqū wayatūkum min fawrihim hādhā yum'did'kum rabbukum bikhamsati ālāfin mina l-malāikati musawwimīna

Yoruba Bẹ́ẹ̀ ni (ó máa tó wa.). Tí ẹ̀yin bá ṣe sùúrú, tí ẹ sì bẹ̀rù Allāhu, tí àwọn (ọ̀tá) bá dé ba yín lójijì, Olúwa yín yóò ràn yín lọ́wọ́ pẹ̀lú ẹgbẹ̀rún máàrún nínú àwọn mọlāika pẹ̀lú àmì ìdánimọ̀ lára wọn.

Verse 126

وَمَا جَعَلَهُ ٱللَّهُ إِلَّا بُشْرَىٰ لَكُمْ وَلِتَطْمَئِنَّ قُلُوبُكُم بِهِۦ ۗ وَمَا ٱلنَّصْرُ إِلَّا مِنْ عِندِ ٱللَّهِ ٱلْعَزِيزِ ٱلْحَكِيمِ

Transliteration wamā jaʿalahu l-lahu illā bush'rā lakum walitaṭma-inna qulūbukum bihi wamā l-naṣru illā min ʿindi l-lahi l-ʿazīzi l-ḥakīmi

Yoruba Allāhu kò ṣe é lásán bí kò ṣe kí ó lè jẹ́ ìró ìdùnnú fún yín àtí nítorí kí ọkàn yín lè balẹ̀ pẹ̀lú rẹ̀. Kò sí àrànṣe lórí ọ̀tá (láti ibì kan kan) bí kò ṣe láti ọ̀dọ̀ Allāhu, Alágbára, Ọlọ́gbọ́n.

Verse 127

لِيَقْطَعَ طَرَفًا مِّنَ ٱلَّذِينَ كَفَرُوٓا۟ أَوْ يَكْبِتَهُمْ فَيَنقَلِبُوا۟ خَآئِبِينَ

Transliteration liyaqṭaʿa ṭarafan mina alladhīna kafarū aw yakbitahum fayanqalibū khāibīna

Yoruba (Allāhu ṣe àrànṣe náà fún yín) nítorí kí Ó lè gé apá kan dànù nínú àwọn tó ṣàì gbàgbọ́, tàbí nítorí kí Ó lè dójú tì wọ́n, tí wọ́n sì máa padà wálé lófo.

Verse 128

لَيْسَ لَكَ مِنَ ٱلْأَمْرِ شَىْءٌ أَوْ يَتُوبَ عَلَيْهِمْ أَوْ يُعَذِّبَهُمْ فَإِنَّهُمْ ظَـٰلِمُونَ

Transliteration laysa laka mina l-amri shayon aw yatūba ʿalayhim aw yuʿadhibahum fa-innahum ẓālimūna

Yoruba Kò sí ohun tó kàn ọ́ nínú ọ̀rọ̀ náà. Yálà (Allāhu) máa gba ìronúpìwàdà wọn tàbí Ó máa jẹ wọ́n níyà; dájúdájú alábòsí ni wọ́n.1

Verse 129

وَلِلَّهِ مَا فِى ٱلسَّمَـٰوَٰتِ وَمَا فِى ٱلْأَرْضِ ۚ يَغْفِرُ لِمَن يَشَآءُ وَيُعَذِّبُ مَن يَشَآءُ ۚ وَٱللَّهُ غَفُورٌ رَّحِيمٌ

Transliteration walillahi mā fī l-samāwāti wamā fī l-arḍi yaghfiru liman yashāu wayuʿadhibu man yashāu wal-lahu ghafūrun raḥīmun

Yoruba Ti Allāhu ni ohunkóhun tó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ohunkóhun tó wà nínú ilẹ̀. Ó ń foríjin ẹni tí Ó bá fẹ́, Ó sì ń jẹ ẹni tí Ó bá fẹ́ níyà. Allāhu sì ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.

Verse 130

يَـٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُوا۟ لَا تَأْكُلُوا۟ ٱلرِّبَوٰٓا۟ أَضْعَـٰفًا مُّضَـٰعَفَةً ۖ وَٱتَّقُوا۟ ٱللَّهَ لَعَلَّكُمْ تُفْلِحُونَ

Transliteration yāayyuhā alladhīna āmanū lā takulū l-riba aḍʿāfan muḍāʿafatan wa-ittaqū l-laha laʿallakum tuf'liḥūna

Yoruba Ẹ̀yin onígbàgbọ́ òdodo, ẹ má ṣe jẹ èlé, àdìpèlé lórí àdìpèlé. Kí ẹ sì bẹ̀rù Allāhu nítorí kí ẹ lè jèrè.

Verse 131

وَٱتَّقُوا۟ ٱلنَّارَ ٱلَّتِىٓ أُعِدَّتْ لِلْكَـٰفِرِينَ

Transliteration wa-ittaqū l-nāra allatī uʿiddat lil'kāfirīna

Yoruba Kí ẹ sì ṣọ́ra fún Iná tí wọ́n ti pa lésè sílẹ̀ de àwọn aláìgbàgbọ́.

Verse 132

وَأَطِيعُوا۟ ٱللَّهَ وَٱلرَّسُولَ لَعَلَّكُمْ تُرْحَمُونَ

Transliteration wa-aṭīʿū l-laha wal-rasūla laʿallakum tur'ḥamūna

Yoruba Kí ẹ tẹ̀lé ti Allāhu àti Òjíṣẹ́ nítorí kí A lè kẹ yín.

Verse 133

۞ وَسَارِعُوٓا۟ إِلَىٰ مَغْفِرَةٍ مِّن رَّبِّكُمْ وَجَنَّةٍ عَرْضُهَا ٱلسَّمَـٰوَٰتُ وَٱلْأَرْضُ أُعِدَّتْ لِلْمُتَّقِينَ

Transliteration wasāriʿū ilā maghfiratin min rabbikum wajannatin ʿarḍuhā l-samāwātu wal-arḍu uʿiddat lil'muttaqīna

Yoruba Ẹ yára wá àforíjìn lọ́dọ̀ Olúwa yín àti Ọgbà Ìdẹ̀ra kan, èyí tí ìbú rẹ̀ tó àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀, tí wọ́n pa lésè sílẹ̀ fún àwọn olùbẹ̀rù (Allāhu).

Verse 134

ٱلَّذِينَ يُنفِقُونَ فِى ٱلسَّرَّآءِ وَٱلضَّرَّآءِ وَٱلْكَـٰظِمِينَ ٱلْغَيْظَ وَٱلْعَافِينَ عَنِ ٱلنَّاسِ ۗ وَٱللَّهُ يُحِبُّ ٱلْمُحْسِنِينَ

Transliteration alladhīna yunfiqūna fī l-sarāi wal-ḍarāi wal-kāẓimīna l-ghayẓa wal-ʿāfīna ʿani l-nāsi wal-lahu yuḥibbu l-muḥ'sinīna

Yoruba Àwọn tó ń ná dúkìá wọn nígbà ìdẹ̀ra àti nígbà ìnira, àwọn tí ń gbé ìbínú mì, àwọn alámòjúúkúrò fún àwọn ènìyàn níbi àṣìṣe; Allāhu nífẹ̀ẹ́ àwọn olùṣe-rere.

Verse 135

وَٱلَّذِينَ إِذَا فَعَلُوا۟ فَـٰحِشَةً أَوْ ظَلَمُوٓا۟ أَنفُسَهُمْ ذَكَرُوا۟ ٱللَّهَ فَٱسْتَغْفَرُوا۟ لِذُنُوبِهِمْ وَمَن يَغْفِرُ ٱلذُّنُوبَ إِلَّا ٱللَّهُ وَلَمْ يُصِرُّوا۟ عَلَىٰ مَا فَعَلُوا۟ وَهُمْ يَعْلَمُونَ

Transliteration wa-alladhīna idhā faʿalū fāḥishatan aw ẓalamū anfusahum dhakarū l-laha fa-is'taghfarū lidhunūbihim waman yaghfiru l-dhunūba illā l-lahu walam yuṣirrū ʿalā mā faʿalū wahum yaʿlamūna

Yoruba Àwọn tí (ó jẹ́ pé) nígbà tí wọ́n bá ṣe ìbàjẹ́ kan tàbí tí wọ́n bá ṣàbòsí sí ẹ̀mí ara wọn, wọ́n á rántí Allāhu, wọ́n á sì tọrọ àforíjìn fún ẹ̀ṣẹ̀ wọn, - Ta sì ni Ó ń forí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ jin (ẹ̀dá) bí kò ṣe Allāhu. Wọn kò sì takú sórí ohun tí wọ́n ṣe nígbà tí wọ́n mọ̀ (pé ẹ̀ṣẹ̀ ni). -

Verse 136

أُو۟لَـٰٓئِكَ جَزَآؤُهُم مَّغْفِرَةٌ مِّن رَّبِّهِمْ وَجَنَّـٰتٌ تَجْرِى مِن تَحْتِهَا ٱلْأَنْهَـٰرُ خَـٰلِدِينَ فِيهَا ۚ وَنِعْمَ أَجْرُ ٱلْعَـٰمِلِينَ

Transliteration ulāika jazāuhum maghfiratun min rabbihim wajannātun tajrī min taḥtihā l-anhāru khālidīna fīhā waniʿ'ma ajru l-ʿāmilīna

Yoruba Àwọn wọ̀nyẹn, ẹ̀san wọn lọ́dọ̀ Olúwa wọn ni àforíjìn àti àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra kan tí àwọn odò ń ṣàn ní ìsàlẹ̀ rẹ̀. Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀. Ẹ̀san olùṣe-iṣẹ́ rere sì dára.

Verse 137

قَدْ خَلَتْ مِن قَبْلِكُمْ سُنَنٌ فَسِيرُوا۟ فِى ٱلْأَرْضِ فَٱنظُرُوا۟ كَيْفَ كَانَ عَـٰقِبَةُ ٱلْمُكَذِّبِينَ

Transliteration qad khalat min qablikum sunanun fasīrū fī l-arḍi fa-unẓurū kayfa kāna ʿāqibatu l-mukadhibīna

Yoruba Àwọn orípa kan kúkú ti lọ ṣíwájú yín. Nítorí náà, ẹ rin ilẹ̀ lọ, kí ẹ wòye sí bí ìgbẹ̀yìn àwọn tó pe òdodo nírọ́ ṣe rí.

Verse 138

هَـٰذَا بَيَانٌ لِّلنَّاسِ وَهُدًى وَمَوْعِظَةٌ لِّلْمُتَّقِينَ

Transliteration hādhā bayānun lilnnāsi wahudan wamawʿiẓatun lil'muttaqīna

Yoruba Èyí ni àlàyé fún àwọn ènìyàn. Ìmọ̀nà àti wáàsí sì ni fún àwọn olùbẹ̀rù (Allāhu).

Verse 139

وَلَا تَهِنُوا۟ وَلَا تَحْزَنُوا۟ وَأَنتُمُ ٱلْأَعْلَوْنَ إِن كُنتُم مُّؤْمِنِينَ

Transliteration walā tahinū walā taḥzanū wa-antumu l-aʿlawna in kuntum mu'minīna

Yoruba Ẹ má ṣe kọ́lẹ, ẹ má ṣe banújẹ́; ẹ̀yin l’ẹ máa lékè tí ẹ bá jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo.

Verse 140

إِن يَمْسَسْكُمْ قَرْحٌ فَقَدْ مَسَّ ٱلْقَوْمَ قَرْحٌ مِّثْلُهُۥ ۚ وَتِلْكَ ٱلْأَيَّامُ نُدَاوِلُهَا بَيْنَ ٱلنَّاسِ وَلِيَعْلَمَ ٱللَّهُ ٱلَّذِينَ ءَامَنُوا۟ وَيَتَّخِذَ مِنكُمْ شُهَدَآءَ ۗ وَٱللَّهُ لَا يُحِبُّ ٱلظَّـٰلِمِينَ

Transliteration in yamsaskum qarḥun faqad massa l-qawma qarḥun mith'luhu watil'ka l-ayāmu nudāwiluhā bayna l-nāsi waliyaʿlama l-lahu alladhīna āmanū wayattakhidha minkum shuhadāa wal-lahu lā yuḥibbu l-ẓālimīna

Yoruba Tí ìpalára kan bá kàn yín, irú ìpalára bẹ́ẹ̀ kúkú ti kan ìjọ kèfèrí. Àwọn ọjọ́ wọ̀nyí, À ń yí i po láààrin àwọn ènìyàn ni. Àti pé nítorí kí Allāhu lè ṣe àfihàn àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo àti nítorí kí Ó lè mú àwọn tó máa kú fún Un nínú yín. Allāhu kò sì nífẹ̀ẹ́ àwọn alábòsí.

Verse 141

وَلِيُمَحِّصَ ٱللَّهُ ٱلَّذِينَ ءَامَنُوا۟ وَيَمْحَقَ ٱلْكَـٰفِرِينَ

Transliteration waliyumaḥḥiṣa l-lahu alladhīna āmanū wayamḥaqa l-kāfirīna

Yoruba Àti pé (ó tún rí bẹ́ẹ̀) nítorí kí Allāhu lè ṣàfọ̀mọ́ àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo àti nítorí kí Ó lè run àwọn aláìgbàgbọ́.

Verse 142

أَمْ حَسِبْتُمْ أَن تَدْخُلُوا۟ ٱلْجَنَّةَ وَلَمَّا يَعْلَمِ ٱللَّهُ ٱلَّذِينَ جَـٰهَدُوا۟ مِنكُمْ وَيَعْلَمَ ٱلصَّـٰبِرِينَ

Transliteration am ḥasib'tum an tadkhulū l-janata walammā yaʿlami l-lahu alladhīna jāhadū minkum wayaʿlama l-ṣābirīna

Yoruba Tàbí ẹ lérò pé ẹ máa wọ inú Ọgbà Ìdẹ̀ra nígbà tí Allāhu kò tí ì ṣàfi hàn àwọn tó máa jagun (ẹ̀sìn) nínú yín, tí kò sì tí ì ṣàfi hàn àwọn onísùúrù.

Verse 143

وَلَقَدْ كُنتُمْ تَمَنَّوْنَ ٱلْمَوْتَ مِن قَبْلِ أَن تَلْقَوْهُ فَقَدْ رَأَيْتُمُوهُ وَأَنتُمْ تَنظُرُونَ

Transliteration walaqad kuntum tamannawna l-mawta min qabli an talqawhu faqad ra-aytumūhu wa-antum tanẓurūna

Yoruba Dájúdájú ẹ ti ń wá ikú (ogun ẹ̀sìn) ṣíwájú kí ẹ tó pàdé rẹ̀. Ẹ kúkú ti rí i (báyìí), ẹ sì ń wòran.

Verse 144

وَمَا مُحَمَّدٌ إِلَّا رَسُولٌ قَدْ خَلَتْ مِن قَبْلِهِ ٱلرُّسُلُ ۚ أَفَإِي۟ن مَّاتَ أَوْ قُتِلَ ٱنقَلَبْتُمْ عَلَىٰٓ أَعْقَـٰبِكُمْ ۚ وَمَن يَنقَلِبْ عَلَىٰ عَقِبَيْهِ فَلَن يَضُرَّ ٱللَّهَ شَيْـًٔا ۗ وَسَيَجْزِى ٱللَّهُ ٱلشَّـٰكِرِينَ

Transliteration wamā muḥammadun illā rasūlun qad khalat min qablihi l-rusulu afa-in māta aw qutila inqalabtum ʿalā aʿqābikum waman yanqalib ʿalā ʿaqibayhi falan yaḍurra l-laha shayan wasayajzī l-lahu l-shākirīna

Yoruba Kí ni (Ànábì) Muhammad bí kò ṣe Òjíṣẹ́, tí àwọn Òjíṣẹ́ kan ti lọ ṣíwájú rẹ̀.Ṣé tí ó bá kú tàbí tí wọ́n bá pa á, ẹ máa pẹ̀yìndà (sẹ́sìn)? Ẹnikẹ́ni tí ó bá pẹ̀yìndà (sẹ́sìn) kò lè kó ìnira kan kan bá Allāhu. Allāhu yó sì san àwọn olùdúpẹ́ ní ẹ̀san rere.

Verse 145

وَمَا كَانَ لِنَفْسٍ أَن تَمُوتَ إِلَّا بِإِذْنِ ٱللَّهِ كِتَـٰبًا مُّؤَجَّلًا ۗ وَمَن يُرِدْ ثَوَابَ ٱلدُّنْيَا نُؤْتِهِۦ مِنْهَا وَمَن يُرِدْ ثَوَابَ ٱلْـَٔاخِرَةِ نُؤْتِهِۦ مِنْهَا ۚ وَسَنَجْزِى ٱلشَّـٰكِرِينَ

Transliteration wamā kāna linafsin an tamūta illā bi-idh'ni l-lahi kitāban mu-ajjalan waman yurid thawāba l-dun'yā nu'tihi min'hā waman yurid thawāba l-ākhirati nu'tihi min'hā wasanajzī l-shākirīna

Yoruba Ẹ̀mí kan kò lè kú àfi pẹ̀lú ìyọ̀ǹda Allāhu. (Ikú jẹ́) àkọsílẹ̀ onígbèdéke. Ẹnikẹ́ni tí ó bá ń fẹ́ ẹ̀san (ní) ayé, A máa fún un nínú rẹ̀(ní ayé). Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì ń fẹ́ ẹ̀san (ní) ọ̀run, A máa fún un nínú rẹ̀ (ní ọ̀run). A ó sì san àwọn olùdúpẹ́ ní ẹ̀san rere.

Verse 146

وَكَأَيِّن مِّن نَّبِىٍّ قَـٰتَلَ مَعَهُۥ رِبِّيُّونَ كَثِيرٌ فَمَا وَهَنُوا۟ لِمَآ أَصَابَهُمْ فِى سَبِيلِ ٱللَّهِ وَمَا ضَعُفُوا۟ وَمَا ٱسْتَكَانُوا۟ ۗ وَٱللَّهُ يُحِبُّ ٱلصَّـٰبِرِينَ

Transliteration waka-ayyin min nabiyyin qātala maʿahu ribbiyyūna kathīrun famā wahanū limā aṣābahum fī sabīli l-lahi wamā ḍaʿufū wamā is'takānū wal-lahu yuḥibbu l-ṣābirīna

Yoruba Mélòó mélòó nínú àwọn Ànábì tí wọ́n ti jagun ẹ̀sìn pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ẹgbẹẹgbẹ̀rún (ọmọ-ẹ̀yìn wọn). Wọn kò ní ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn nípa ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí wọn ní ojú ogun ẹ̀sìn Allāhu. Wọn kò kọ́lẹ, wọn kò sì jura wọn sílẹ̀ fún ọ̀tá ẹ̀sìn. Allāhu sì nífẹ̀ẹ́ àwọn onísùúrù.

Verse 147

وَمَا كَانَ قَوْلَهُمْ إِلَّآ أَن قَالُوا۟ رَبَّنَا ٱغْفِرْ لَنَا ذُنُوبَنَا وَإِسْرَافَنَا فِىٓ أَمْرِنَا وَثَبِّتْ أَقْدَامَنَا وَٱنصُرْنَا عَلَى ٱلْقَوْمِ ٱلْكَـٰفِرِينَ

Transliteration wamā kāna qawlahum illā an qālū rabbanā igh'fir lanā dhunūbanā wa-is'rāfanā fī amrinā wathabbit aqdāmanā wa-unṣur'nā ʿalā l-qawmi l-kāfirīna

Yoruba Kò sì sí ohun kan tí wọ́n sọ tayọ pé wọ́n sọ pé: “Olúwa wa forí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa àti àṣejù wa nínú ọ̀rọ̀ (àwọn àṣìṣe) wa jìn wá, mú ẹsẹ̀ wa dúró ṣinṣin, kí O sì ṣe àrànṣe fún wa lórí ìjọ aláìgbàgbọ́.”

Verse 148

فَـَٔاتَىٰهُمُ ٱللَّهُ ثَوَابَ ٱلدُّنْيَا وَحُسْنَ ثَوَابِ ٱلْـَٔاخِرَةِ ۗ وَٱللَّهُ يُحِبُّ ٱلْمُحْسِنِينَ

Transliteration faātāhumu l-lahu thawāba l-dun'yā waḥus'na thawābi l-ākhirati wal-lahu yuḥibbu l-muḥ'sinīna

Yoruba Nítorí náà, Allāhu fún wọn ní ẹ̀san ayé àti dáadáa ẹ̀san ọ̀run. Allāhu sì nífẹ̀ẹ́ àwọn olùṣe-rere.

Verse 149

يَـٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُوٓا۟ إِن تُطِيعُوا۟ ٱلَّذِينَ كَفَرُوا۟ يَرُدُّوكُمْ عَلَىٰٓ أَعْقَـٰبِكُمْ فَتَنقَلِبُوا۟ خَـٰسِرِينَ

Transliteration yāayyuhā alladhīna āmanū in tuṭīʿū alladhīna kafarū yaruddūkum ʿalā aʿqābikum fatanqalibū khāsirīna

Yoruba Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, tí ẹ bá tẹ̀lé àwọn tó ṣàì gbàgbọ́, wọ́n máa yi yín lẹ́sẹ̀ padà kúrò nínú ẹ̀sìn. Nígbà náà, ẹ máa padà di ẹni òfò (sínú àìgbàgbọ́).

Verse 150

بَلِ ٱللَّهُ مَوْلَىٰكُمْ ۖ وَهُوَ خَيْرُ ٱلنَّـٰصِرِينَ

Transliteration bali l-lahu mawlākum wahuwa khayru l-nāṣirīna

Yoruba Allāhu sì ni Alárànṣe yín.Ó sì lóore jùlọ nínú àwọn alárànṣe.2

Verse 151

سَنُلْقِى فِى قُلُوبِ ٱلَّذِينَ كَفَرُوا۟ ٱلرُّعْبَ بِمَآ أَشْرَكُوا۟ بِٱللَّهِ مَا لَمْ يُنَزِّلْ بِهِۦ سُلْطَـٰنًا ۖ وَمَأْوَىٰهُمُ ٱلنَّارُ ۚ وَبِئْسَ مَثْوَى ٱلظَّـٰلِمِينَ

Transliteration sanul'qī fī qulūbi alladhīna kafarū l-ruʿ'ba bimā ashrakū bil-lahi mā lam yunazzil bihi sul'ṭānan wamawāhumu l-nāru wabi'sa mathwā l-ẓālimīna

Yoruba A máa fi ẹ̀rù jẹ̀jẹ̀ sínú ọkàn àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ nítorí pé wọ́n bá Allāhu wá akẹgbẹ́, èyí tí kò sọ ẹ̀rí kan kalẹ̀ fún. Iná ni ibùgbé wọn; ilé àwọn alábòsí sì burú.

Verse 152

وَلَقَدْ صَدَقَكُمُ ٱللَّهُ وَعْدَهُۥٓ إِذْ تَحُسُّونَهُم بِإِذْنِهِۦ ۖ حَتَّىٰٓ إِذَا فَشِلْتُمْ وَتَنَـٰزَعْتُمْ فِى ٱلْأَمْرِ وَعَصَيْتُم مِّنۢ بَعْدِ مَآ أَرَىٰكُم مَّا تُحِبُّونَ ۚ مِنكُم مَّن يُرِيدُ ٱلدُّنْيَا وَمِنكُم مَّن يُرِيدُ ٱلْـَٔاخِرَةَ ۚ ثُمَّ صَرَفَكُمْ عَنْهُمْ لِيَبْتَلِيَكُمْ ۖ وَلَقَدْ عَفَا عَنكُمْ ۗ وَٱللَّهُ ذُو فَضْلٍ عَلَى ٱلْمُؤْمِنِينَ

Transliteration walaqad ṣadaqakumu l-lahu waʿdahu idh taḥussūnahum bi-idh'nihi ḥattā idhā fashil'tum watanāzaʿtum fī l-amri waʿaṣaytum min baʿdi mā arākum mā tuḥibbūna minkum man yurīdu l-dun'yā waminkum man yurīdu l-ākhirata thumma ṣarafakum ʿanhum liyabtaliyakum walaqad ʿafā ʿankum wal-lahu dhū faḍlin ʿalā l-mu'minīna

Yoruba Dájúdájú Allāhu ti mú àdéhùn Rẹ̀ ṣẹ fún yín nígbà tí ẹ̀ ń pa wọ́n pẹ̀lú ìyọ̀ǹda Rẹ̀, títí di ìgbà tí ẹ fi ṣojo, tí ẹ sì ń jiyàn sí ọ̀rọ̀. Ẹ sì yapa àṣẹ (Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -) lẹ́yìn tí Allāhu fi ohun tí ẹ nífẹ̀ẹ́ sí hàn yín. - Ó wà nínú yín ẹni tí ń fẹ́ ayé, ó sì ń bẹ nínú yín ẹni tí ń fẹ́ ọ̀run. - Lẹ́yìn náà, (Allāhu) yí ojú yín kúrò ní ọ̀dọ̀ wọn nítorí kí Ó lè dan yín wò. Ó sì ti ṣàmójú kúrò fún yín; Allāhu ni Olóore àjùlọ lórí àwọn onígbàgbọ́ òdodo.

Verse 153

۞ إِذْ تُصْعِدُونَ وَلَا تَلْوُۥنَ عَلَىٰٓ أَحَدٍ وَٱلرَّسُولُ يَدْعُوكُمْ فِىٓ أُخْرَىٰكُمْ فَأَثَـٰبَكُمْ غَمًّۢا بِغَمٍّ لِّكَيْلَا تَحْزَنُوا۟ عَلَىٰ مَا فَاتَكُمْ وَلَا مَآ أَصَـٰبَكُمْ ۗ وَٱللَّهُ خَبِيرٌۢ بِمَا تَعْمَلُونَ

Transliteration idh tuṣ'ʿidūna walā talwūna ʿalā aḥadin wal-rasūlu yadʿūkum fī ukh'rākum fa-athābakum ghamman bighammin likaylā taḥzanū ʿalā mā fātakum walā mā aṣābakum wal-lahu khabīrun bimā taʿmalūna

Yoruba (Ẹ rántí) nígbà tí ẹ̀ ń gùnkè sá lọ, tí ẹ̀yin kò sì bojú wo ẹnì kan kan mọ́ lẹ́yìn, Òjíṣẹ́ sì ń pè yín láti ẹ̀yìn yín. Nítorí náà, (Allāhu) fi ìbànújẹ́(pípa tí àwọn ọ̀ṣẹbọ pa àwọn kan láààrin yín) san yín ní ẹ̀san ìbànújẹ́ (tí ẹ fi kan Ànábì nípasẹ̀ àìtẹ̀lé àṣẹ rẹ̀ lójú ogun ’Uhd. (Ó rí bẹ́ẹ̀) nítorí kí ẹ má baà banújẹ́ lórí ohun tí ó bọ́ fún yín àti ohun tí ó ṣẹlẹ̀ si yín. Allāhu ni Alámọ̀tán nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.

Verse 154

ثُمَّ أَنزَلَ عَلَيْكُم مِّنۢ بَعْدِ ٱلْغَمِّ أَمَنَةً نُّعَاسًا يَغْشَىٰ طَآئِفَةً مِّنكُمْ ۖ وَطَآئِفَةٌ قَدْ أَهَمَّتْهُمْ أَنفُسُهُمْ يَظُنُّونَ بِٱللَّهِ غَيْرَ ٱلْحَقِّ ظَنَّ ٱلْجَـٰهِلِيَّةِ ۖ يَقُولُونَ هَل لَّنَا مِنَ ٱلْأَمْرِ مِن شَىْءٍ ۗ قُلْ إِنَّ ٱلْأَمْرَ كُلَّهُۥ لِلَّهِ ۗ يُخْفُونَ فِىٓ أَنفُسِهِم مَّا لَا يُبْدُونَ لَكَ ۖ يَقُولُونَ لَوْ كَانَ لَنَا مِنَ ٱلْأَمْرِ شَىْءٌ مَّا قُتِلْنَا هَـٰهُنَا ۗ قُل لَّوْ كُنتُمْ فِى بُيُوتِكُمْ لَبَرَزَ ٱلَّذِينَ كُتِبَ عَلَيْهِمُ ٱلْقَتْلُ إِلَىٰ مَضَاجِعِهِمْ ۖ وَلِيَبْتَلِىَ ٱللَّهُ مَا فِى صُدُورِكُمْ وَلِيُمَحِّصَ مَا فِى قُلُوبِكُمْ ۗ وَٱللَّهُ عَلِيمٌۢ بِذَاتِ ٱلصُّدُورِ

Transliteration thumma anzala ʿalaykum min baʿdi l-ghami amanatan nuʿāsan yaghshā ṭāifatan minkum waṭāifatun qad ahammathum anfusuhum yaẓunnūna bil-lahi ghayra l-ḥaqi ẓanna l-jāhiliyati yaqūlūna hal lanā mina l-amri min shayin qul inna l-amra kullahu lillahi yukh'fūna fī anfusihim mā lā yub'dūna laka yaqūlūna law kāna lanā mina l-amri shayon mā qutil'nā hāhunā qul law kuntum fī buyūtikum labaraza alladhīna kutiba ʿalayhimu l-qatlu ilā maḍājiʿihim waliyabtaliya l-lahu mā fī ṣudūrikum waliyumaḥḥiṣa mā fī qulūbikum wal-lahu ʿalīmun bidhāti l-ṣudūri

Yoruba Lẹ́yìn náà, Ó sọ ìfàyàbalẹ̀ kalẹ̀ fún yín lẹ́yìn ìbànújẹ́; òògbé ta igun kan lọ nínú yín. Igun kan tí ẹ̀mí ara wọn sì ti kó èrò bá, tí wọ́n sì ń ní èròkérò sí Allāhu lọ́nà àìtọ́, èròkérò ìgbà àìmọ̀kan, wọ́n sì ń wí pé: “Ǹjẹ́ a ní àṣẹ kan (tí a lè mú wá) lórí ọ̀rọ̀ náà bí!” Sọ pé: “Dájúdájú gbogbo àṣẹ ń jẹ́ ti Allāhu pátápátá.” Wọ́n ń fi pamọ́ sínú ọkàn wọn ohun tí wọn kò lè ṣàfi hàn rẹ̀ fún ọ. Wọ́n ń wí pé: “Tí ó bá jẹ́ pé a ní àṣẹ kan lórí ọ̀rọ̀ náà ni, wọn ìbá tí pa wá síbí.” Sọ pé: “Tí ó bá jẹ́ pé ẹ wà nínú ilé yín, àwọn tí A ti kọ àkọọ́lè pípa sí ibùjàgun wọn mọ ìbá kúkú jáde lọ síbẹ̀.”(Ogun yìí rí bẹ́ẹ̀) nítorí kí Allāhu lè gbìdánwò ohun tí ń bẹ nínú igbá-àyà yín àti nítorí kí Ó lè ṣàfọ̀mọ́ ohun tí ń bẹ nínú ọkàn yín. Allāhu sì ni Onímọ̀ nípa ohun tí ń bẹ nínú igbá-àyà ẹ̀dá.

Verse 155

إِنَّ ٱلَّذِينَ تَوَلَّوْا۟ مِنكُمْ يَوْمَ ٱلْتَقَى ٱلْجَمْعَانِ إِنَّمَا ٱسْتَزَلَّهُمُ ٱلشَّيْطَـٰنُ بِبَعْضِ مَا كَسَبُوا۟ ۖ وَلَقَدْ عَفَا ٱللَّهُ عَنْهُمْ ۗ إِنَّ ٱللَّهَ غَفُورٌ حَلِيمٌ

Transliteration inna alladhīna tawallaw minkum yawma l-taqā l-jamʿāni innamā is'tazallahumu l-shayṭānu bibaʿḍi mā kasabū walaqad ʿafā l-lahu ʿanhum inna l-laha ghafūrun ḥalīmun

Yoruba Dájúdájú àwọn tó pẹ̀yìndà nínú yín ní ọjọ́ tí ìjọ méjì pàdé, dájúdájú Èṣù l’ó yẹ̀ wọ́n lẹ́sẹ̀ nítorí apá kan ohun tí wọ́n ṣe níṣẹ́. Allāhu sì kúkú ti ṣàmójú kúrò fún wọn. Dájúdájú Allāhu ni Aláforíjìn, Aláfaradà.

Verse 156

يَـٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُوا۟ لَا تَكُونُوا۟ كَٱلَّذِينَ كَفَرُوا۟ وَقَالُوا۟ لِإِخْوَٰنِهِمْ إِذَا ضَرَبُوا۟ فِى ٱلْأَرْضِ أَوْ كَانُوا۟ غُزًّى لَّوْ كَانُوا۟ عِندَنَا مَا مَاتُوا۟ وَمَا قُتِلُوا۟ لِيَجْعَلَ ٱللَّهُ ذَٰلِكَ حَسْرَةً فِى قُلُوبِهِمْ ۗ وَٱللَّهُ يُحْىِۦ وَيُمِيتُ ۗ وَٱللَّهُ بِمَا تَعْمَلُونَ بَصِيرٌ

Transliteration yāayyuhā alladhīna āmanū lā takūnū ka-alladhīna kafarū waqālū li-ikh'wānihim idhā ḍarabū fī l-arḍi aw kānū ghuzzan law kānū ʿindanā mā mātū wamā qutilū liyajʿala l-lahu dhālika ḥasratan fī qulūbihim wal-lahu yuḥ'yī wayumītu wal-lahu bimā taʿmalūna baṣīrun

Yoruba Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ má ṣe dà bí àwọn tó ṣàì gbàgbọ́, tí wọ́n sọ fún àwọn ọmọ ìyá wọn, nígbà tí wọ́n ń rìn kiri ní orí ilẹ̀tàbí (nígbà) tí wọ́n ń jagun, pé: “Tí ó bá jẹ́ pé wọ́n ń bẹ ní ọ̀dọ̀ wa ni, wọn ìbá tí kú, àti pé wọn ìbá tí pa wọ́n.” (Wọ́n wí bẹ́ẹ̀) nítorí kí Allāhu lè fi ìyẹn ṣe àbámọ̀ sínú ọkàn wọn. Allāhu l’Ó ń sọ ẹ̀dá di alààyè. Ó sì ń sọ ẹ̀dá di òkú. Allāhu sì ni Olùríran nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.

Verse 157

وَلَئِن قُتِلْتُمْ فِى سَبِيلِ ٱللَّهِ أَوْ مُتُّمْ لَمَغْفِرَةٌ مِّنَ ٱللَّهِ وَرَحْمَةٌ خَيْرٌ مِّمَّا يَجْمَعُونَ

Transliteration wala-in qutil'tum fī sabīli l-lahi aw muttum lamaghfiratun mina l-lahi waraḥmatun khayrun mimmā yajmaʿūna

Yoruba Dájúdájú tí wọ́n bá pa yín s’ójú ogun ẹ̀sìn Allāhu tàbí ẹ kú (sínú ilé), dájúdájú àforíjìn àti àánú láti ọ̀dọ̀ Allāhu lóore ju ohun tí ẹ̀ ń kójọ (nílé ayé).

Verse 158

وَلَئِن مُّتُّمْ أَوْ قُتِلْتُمْ لَإِلَى ٱللَّهِ تُحْشَرُونَ

Transliteration wala-in muttum aw qutil'tum la-ilā l-lahi tuḥ'sharūna

Yoruba Dájúdájú tí ẹ bá kú (sínú ilé) tàbí wọ́n pa yín (s’ójú ogun ẹ̀sìn), dájúdájú ọ̀dọ̀ Allāhu ni wọn máa ko yín jọ sí.

Verse 159

فَبِمَا رَحْمَةٍ مِّنَ ٱللَّهِ لِنتَ لَهُمْ ۖ وَلَوْ كُنتَ فَظًّا غَلِيظَ ٱلْقَلْبِ لَٱنفَضُّوا۟ مِنْ حَوْلِكَ ۖ فَٱعْفُ عَنْهُمْ وَٱسْتَغْفِرْ لَهُمْ وَشَاوِرْهُمْ فِى ٱلْأَمْرِ ۖ فَإِذَا عَزَمْتَ فَتَوَكَّلْ عَلَى ٱللَّهِ ۚ إِنَّ ٱللَّهَ يُحِبُّ ٱلْمُتَوَكِّلِينَ

Transliteration fabimā raḥmatin mina l-lahi linta lahum walaw kunta faẓẓan ghalīẓa l-qalbi la-infaḍḍū min ḥawlika fa-uʿ'fu ʿanhum wa-is'taghfir lahum washāwir'hum fī l-amri fa-idhā ʿazamta fatawakkal ʿalā l-lahi inna l-laha yuḥibbu l-mutawakilīna

Yoruba Pẹ̀lú ìkẹ́ kan láti ọ̀dọ̀ Allāhu l’ó kúkú fi rọ̀ fún wọn; tí ó bá jẹ́ pé o jẹ́ ẹni burúkú, ọlọ́kàn líle, wọn ìbá ti túká kúrò lọ́dọ̀ rẹ. Ṣàmójú kúrò fún wọn, bá wọn tọrọ àforíjìn, kí o sì bá wọn jíròrò lórí ọ̀rọ̀. Tí o bá sì pinnu (ọ̀rọ̀ kan), kí o gbáralé Allāhu. Dájúdájú Allāhu nífẹ̀ẹ́ àwọn olùgbáralé E.

Verse 160

إِن يَنصُرْكُمُ ٱللَّهُ فَلَا غَالِبَ لَكُمْ ۖ وَإِن يَخْذُلْكُمْ فَمَن ذَا ٱلَّذِى يَنصُرُكُم مِّنۢ بَعْدِهِۦ ۗ وَعَلَى ٱللَّهِ فَلْيَتَوَكَّلِ ٱلْمُؤْمِنُونَ

Transliteration in yanṣur'kumu l-lahu falā ghāliba lakum wa-in yakhdhul'kum faman dhā alladhī yanṣurukum min baʿdihi waʿalā l-lahi falyatawakkali l-mu'minūna

Yoruba Tí Allāhu bá ṣe àrànṣe fún yín, kò sí ẹni tí ó máa borí yín. Tí Ó bá sì yẹpẹrẹ yín, ta sì ni ẹni tí ó máa ṣe àrànṣe fún yín lẹ́yìn Rẹ̀? Allāhu ni kí àwọn onígbàgbọ́ òdodo gbáralé.

Verse 161

وَمَا كَانَ لِنَبِىٍّ أَن يَغُلَّ ۚ وَمَن يَغْلُلْ يَأْتِ بِمَا غَلَّ يَوْمَ ٱلْقِيَـٰمَةِ ۚ ثُمَّ تُوَفَّىٰ كُلُّ نَفْسٍ مَّا كَسَبَتْ وَهُمْ لَا يُظْلَمُونَ

Transliteration wamā kāna linabiyyin an yaghulla waman yaghlul yati bimā ghalla yawma l-qiyāmati thumma tuwaffā kullu nafsin mā kasabat wahum lā yuẓ'lamūna

Yoruba Kò lẹ́tọ̀ọ́ fún Ànábì kan láti jí mú nínú ọrọ̀ ogun ṣíwájú kí wọ́n tó pín in. Ẹnikẹ́ní tí ó bá jí ọrọ̀ ogun mú ṣíwájú kí wọ́n tó pín in, ó máa dá ohun tí ó jí mú nínú ọrọ̀ ogun náà padà ní Ọjọ́ Àjíǹde. Lẹ́yìn náà, A óò san ẹ̀mí kọ̀ọ̀kan ní ẹ̀san ohun tí ó ṣe níṣẹ́ ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́. A ò sì níí ṣe àbòsí sí wọn.

Verse 162

أَفَمَنِ ٱتَّبَعَ رِضْوَٰنَ ٱللَّهِ كَمَنۢ بَآءَ بِسَخَطٍ مِّنَ ٱللَّهِ وَمَأْوَىٰهُ جَهَنَّمُ ۚ وَبِئْسَ ٱلْمَصِيرُ

Transliteration afamani ittabaʿa riḍ'wāna l-lahi kaman bāa bisakhaṭin mina l-lahi wamawāhu jahannamu wabi'sa l-maṣīru

Yoruba Ṣé ẹni tí ó (ṣiṣẹ́) tọ ìyọ́nú Allāhu dà bí ẹni tí ó padà wálé pẹ̀lú ìbínú láti ọ̀dọ̀ Allāhu, ibùgbé rẹ̀ sì ni iná Jahanamọ? Ìkángun náà sì burú.

Verse 163

هُمْ دَرَجَـٰتٌ عِندَ ٱللَّهِ ۗ وَٱللَّهُ بَصِيرٌۢ بِمَا يَعْمَلُونَ

Transliteration hum darajātun ʿinda l-lahi wal-lahu baṣīrun bimā yaʿmalūna

Yoruba (Èkínní kejì èrò inú Ọgbà Ìdẹ̀ra àti èrò inú Iná ni) wọ́n ní ipò (ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀) ní ọ̀dọ̀ Allāhu. Allāhu sì ni Olùríran nípa ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́.

Verse 164

لَقَدْ مَنَّ ٱللَّهُ عَلَى ٱلْمُؤْمِنِينَ إِذْ بَعَثَ فِيهِمْ رَسُولًا مِّنْ أَنفُسِهِمْ يَتْلُوا۟ عَلَيْهِمْ ءَايَـٰتِهِۦ وَيُزَكِّيهِمْ وَيُعَلِّمُهُمُ ٱلْكِتَـٰبَ وَٱلْحِكْمَةَ وَإِن كَانُوا۟ مِن قَبْلُ لَفِى ضَلَـٰلٍ مُّبِينٍ

Transliteration laqad manna l-lahu ʿalā l-mu'minīna idh baʿatha fīhim rasūlan min anfusihim yatlū ʿalayhim āyātihi wayuzakkīhim wayuʿallimuhumu l-kitāba wal-ḥik'mata wa-in kānū min qablu lafī ḍalālin mubīnin

Yoruba Allāhu kúkú ti ṣe oore fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo nígbà tí Ó fi lè gbé Òjíṣẹ́ kan dìde sí wọn láààrin ara wọn. (Òjíṣẹ́ náà) ń ké àwọn āyah Rẹ̀ fún wọn. Ó ń fọ̀ wọ́n mọ́ (nínú ẹ̀ṣẹ̀). Ó sì ń kọ́ wọn ní Tírà (al-Ƙur’ān) àti òye ìjìnlẹ̀ (sunnah), bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀ wọ́n wà nínú ìṣìnà pọ́nńbélé.

Verse 165

أَوَلَمَّآ أَصَـٰبَتْكُم مُّصِيبَةٌ قَدْ أَصَبْتُم مِّثْلَيْهَا قُلْتُمْ أَنَّىٰ هَـٰذَا ۖ قُلْ هُوَ مِنْ عِندِ أَنفُسِكُمْ ۗ إِنَّ ٱللَّهَ عَلَىٰ كُلِّ شَىْءٍ قَدِيرٌ

Transliteration awalammā aṣābatkum muṣībatun qad aṣabtum mith'layhā qul'tum annā hādhā qul huwa min ʿindi anfusikum inna l-laha ʿalā kulli shayin qadīrun

Yoruba Ṣé gbogbo ìgbà tí àdánwò kan bá kàn yín, tí ẹ sì ti fi méjì irú rẹ̀ (kan àwọn kèfèrí), ni ẹ̀yin yóò máa sọ pé: “Ọ̀nà wo ni èyí gbà ṣẹlẹ̀ sí wa?” Sọ pé: “Ó wá láti ọ̀dọ̀ ara yín.” Dájúdájú Allāhu ni Alágbára lórí gbogbo n̄ǹkan.

Verse 166

وَمَآ أَصَـٰبَكُمْ يَوْمَ ٱلْتَقَى ٱلْجَمْعَانِ فَبِإِذْنِ ٱللَّهِ وَلِيَعْلَمَ ٱلْمُؤْمِنِينَ

Transliteration wamā aṣābakum yawma l-taqā l-jamʿāni fabi-idh'ni l-lahi waliyaʿlama l-mu'minīna

Yoruba Ohun tí ó ṣẹlẹ̀ si yín ní ọjọ́ tí ikọ̀ ogun méjèèjì pàdé, (ó ṣẹlẹ̀) pẹ̀lú ìyọ̀ǹda Allāhu. Àti pé nítorí kí Ó lè ṣàfi hàn àwọn onígbàgbọ́ òdodo ni.

Verse 167

وَلِيَعْلَمَ ٱلَّذِينَ نَافَقُوا۟ ۚ وَقِيلَ لَهُمْ تَعَالَوْا۟ قَـٰتِلُوا۟ فِى سَبِيلِ ٱللَّهِ أَوِ ٱدْفَعُوا۟ ۖ قَالُوا۟ لَوْ نَعْلَمُ قِتَالًا لَّٱتَّبَعْنَـٰكُمْ ۗ هُمْ لِلْكُفْرِ يَوْمَئِذٍ أَقْرَبُ مِنْهُمْ لِلْإِيمَـٰنِ ۚ يَقُولُونَ بِأَفْوَٰهِهِم مَّا لَيْسَ فِى قُلُوبِهِمْ ۗ وَٱللَّهُ أَعْلَمُ بِمَا يَكْتُمُونَ

Transliteration waliyaʿlama alladhīna nāfaqū waqīla lahum taʿālaw qātilū fī sabīli l-lahi awi id'faʿū qālū law naʿlamu qitālan la-ittabaʿnākum hum lil'kuf'ri yawma-idhin aqrabu min'hum lil'īmāni yaqūlūna bi-afwāhihim mā laysa fī qulūbihim wal-lahu aʿlamu bimā yaktumūna

Yoruba (Ó tún rí bẹ́ẹ̀) nítorí kí Ó lè ṣàfi hàn àwọn tó ṣọ̀bẹ-ṣèlu (nínú àwọn mùsùlùmí). (Àwọn onígbàgbọ́ òdodo) sì sọ fún wọn pé: “Ẹ máa bọ̀, kí á lọ jagun fún ẹ̀sìn Allāhu tàbí ẹ wá dáàbò bo ẹ̀mí ara yín.” Wọ́n wí pé: “Àwa ìbá mọ ogun-ún jà àwa ìbá tẹ̀lé yín.” Wọ́n súnmọ́ àìgbàgbọ́ ju ìgbàgbọ́ ní ọjọ́ yẹn. Wọ́n ń fi ẹnu wọn sọ ohun tí kò sí nínú ọkàn wọn. Allāhu sì nímọ̀ jùlọ nípa ohun tí wọ́n ń fi pamọ́.

Verse 168

ٱلَّذِينَ قَالُوا۟ لِإِخْوَٰنِهِمْ وَقَعَدُوا۟ لَوْ أَطَاعُونَا مَا قُتِلُوا۟ ۗ قُلْ فَٱدْرَءُوا۟ عَنْ أَنفُسِكُمُ ٱلْمَوْتَ إِن كُنتُمْ صَـٰدِقِينَ

Transliteration alladhīna qālū li-ikh'wānihim waqaʿadū law aṭāʿūnā mā qutilū qul fa-id'raū ʿan anfusikumu l-mawta in kuntum ṣādiqīna

Yoruba Àwọn tó sọ nípa àwọn ọmọ ìyá wọn (tó kú s’ójú ogun ẹ̀sìn) pé – tí àwọn sì jòkóò kalẹ̀ sílé (ní tiwọn)-, "Tí ó bá jẹ́ pé wọ́n tẹ̀lé tiwa ni, wọn ìbá tí pa wọ́n." Sọ pé: “Ẹ yẹkú dànù fún ẹ̀mí yín tí ẹ bá jẹ́ olódodo.”

Verse 169

وَلَا تَحْسَبَنَّ ٱلَّذِينَ قُتِلُوا۟ فِى سَبِيلِ ٱللَّهِ أَمْوَٰتًۢا ۚ بَلْ أَحْيَآءٌ عِندَ رَبِّهِمْ يُرْزَقُونَ

Transliteration walā taḥsabanna alladhīna qutilū fī sabīli l-lahi amwātan bal aḥyāon ʿinda rabbihim yur'zaqūna

Yoruba Ẹ má ṣe lérò pé òkú (ìyà) ni àwọn tí wọ́n pa s’ójú ogun ẹ̀sìn Allāhu, bí kò ṣe pé alààyè (ẹni ìkẹ́) ni wọ́n. Wọ́n sì ń pèsè ìjẹ-ìmu fún wọn lọ́dọ̀ Olúwa wọn.1

Verse 170

فَرِحِينَ بِمَآ ءَاتَىٰهُمُ ٱللَّهُ مِن فَضْلِهِۦ وَيَسْتَبْشِرُونَ بِٱلَّذِينَ لَمْ يَلْحَقُوا۟ بِهِم مِّنْ خَلْفِهِمْ أَلَّا خَوْفٌ عَلَيْهِمْ وَلَا هُمْ يَحْزَنُونَ

Transliteration fariḥīna bimā ātāhumu l-lahu min faḍlihi wayastabshirūna bi-alladhīna lam yalḥaqū bihim min khalfihim allā khawfun ʿalayhim walā hum yaḥzanūna

Yoruba Wọ́n ń dunnú nítorí ohun tí Allāhu fún wọn nínú oore-àjùlọ Rẹ̀. Wọ́n sì ń yọ̀ fún àwọn tí kò tí ì pàdé wọn nínú àwọn tí wọ́n fi sílẹ̀ pé: “Kò sí ìpáyà fún wọn. Wọn kò sì níí banújẹ́.”

Verse 171

۞ يَسْتَبْشِرُونَ بِنِعْمَةٍ مِّنَ ٱللَّهِ وَفَضْلٍ وَأَنَّ ٱللَّهَ لَا يُضِيعُ أَجْرَ ٱلْمُؤْمِنِينَ

Transliteration yastabshirūna biniʿ'matin mina l-lahi wafaḍlin wa-anna l-laha lā yuḍīʿu ajra l-mu'minīna

Yoruba Wọ́n ń bá wọn yọ̀ fún ìkẹ́ àti oore-àjùlọ (tí ń dúró dè wọ́n) lọ́dọ̀ Allāhu. Àti pé dájúdájú Allāhu kò níí fi ẹ̀san àwọn onígbàgbọ́ òdodo ráre.

Verse 172

ٱلَّذِينَ ٱسْتَجَابُوا۟ لِلَّهِ وَٱلرَّسُولِ مِنۢ بَعْدِ مَآ أَصَابَهُمُ ٱلْقَرْحُ ۚ لِلَّذِينَ أَحْسَنُوا۟ مِنْهُمْ وَٱتَّقَوْا۟ أَجْرٌ عَظِيمٌ

Transliteration alladhīna is'tajābū lillahi wal-rasūli min baʿdi mā aṣābahumu l-qarḥu lilladhīna aḥsanū min'hum wa-ittaqaw ajrun ʿaẓīmun

Yoruba (Àwọn ni) àwọn tó jẹ́pè Allāhu àti Òjíṣẹ́ lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n ti f’ara gbọgbẹ́. Ẹ̀san ńlá wà fún àwọn tó ṣe rere, tí wọ́n sì bẹ̀rù (Allāhu) nínú wọn.

Verse 173

ٱلَّذِينَ قَالَ لَهُمُ ٱلنَّاسُ إِنَّ ٱلنَّاسَ قَدْ جَمَعُوا۟ لَكُمْ فَٱخْشَوْهُمْ فَزَادَهُمْ إِيمَـٰنًا وَقَالُوا۟ حَسْبُنَا ٱللَّهُ وَنِعْمَ ٱلْوَكِيلُ

Transliteration alladhīna qāla lahumu l-nāsu inna l-nāsa qad jamaʿū lakum fa-ikh'shawhum fazādahum īmānan waqālū ḥasbunā l-lahu waniʿ'ma l-wakīlu

Yoruba (Àwọn ni) àwọn tí àwọn ènìyàn wí fún pé: “Wọ́n mà ti kóra jọ dè yín, nítorí náà ẹ bẹ̀rù wọn.” (Èyí) lékún ìgbàgbọ́ òdodo wọn. Wọ́n sì sọ pé: “Allāhu tó fún wa. Ó sì dára ni Alámòójútó.”

Verse 174

فَٱنقَلَبُوا۟ بِنِعْمَةٍ مِّنَ ٱللَّهِ وَفَضْلٍ لَّمْ يَمْسَسْهُمْ سُوٓءٌ وَٱتَّبَعُوا۟ رِضْوَٰنَ ٱللَّهِ ۗ وَٱللَّهُ ذُو فَضْلٍ عَظِيمٍ

Transliteration fa-inqalabū biniʿ'matin mina l-lahi wafaḍlin lam yamsashum sūon wa-ittabaʿū riḍ'wāna l-lahi wal-lahu dhū faḍlin ʿaẓīmin

Yoruba Nítorí náà, wọ́n padà délé pẹ̀lú ìkẹ́ àti oore-àjùlọ láti ọ̀dọ̀ Allāhu. Aburú kan kò sì kàn wọ́n. Àti pé wọ́n (ṣiṣẹ́) tọ ìyọ́nú Allāhu. Allāhu sì ni Olóore ńlá.

Verse 175

إِنَّمَا ذَٰلِكُمُ ٱلشَّيْطَـٰنُ يُخَوِّفُ أَوْلِيَآءَهُۥ فَلَا تَخَافُوهُمْ وَخَافُونِ إِن كُنتُم مُّؤْمِنِينَ

Transliteration innamā dhālikumu l-shayṭānu yukhawwifu awliyāahu falā takhāfūhum wakhāfūni in kuntum mu'minīna

Yoruba Dájúdájú ìyẹn ni Èṣù, tí ó ń fi àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ dẹ́rù bà yín. Nítorí náà, ẹ má ṣe bẹ̀rù wọn. Kí ẹ sì bẹ̀rù Mi tí ẹ bá jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo.

Verse 176

وَلَا يَحْزُنكَ ٱلَّذِينَ يُسَـٰرِعُونَ فِى ٱلْكُفْرِ ۚ إِنَّهُمْ لَن يَضُرُّوا۟ ٱللَّهَ شَيْـًٔا ۗ يُرِيدُ ٱللَّهُ أَلَّا يَجْعَلَ لَهُمْ حَظًّا فِى ٱلْـَٔاخِرَةِ ۖ وَلَهُمْ عَذَابٌ عَظِيمٌ

Transliteration walā yaḥzunka alladhīna yusāriʿūna fī l-kuf'ri innahum lan yaḍurrū l-laha shayan yurīdu l-lahu allā yajʿala lahum ḥaẓẓan fī l-ākhirati walahum ʿadhābun ʿaẓīmun

Yoruba Má ṣe jẹ́ kí àwọn tí ń sáré kó sínú àìgbàgbọ́ kó ìbànújẹ́ bá ọ. Dájúdájú wọn kò lè kó ìnira kan kan bá Allāhu. Allāhu kò fẹ́ kí ìpín kan nínú oore wà fún wọn ní ọ̀run (ni); ìyà ńlá sì ń bẹ fún wọn.

Verse 177

إِنَّ ٱلَّذِينَ ٱشْتَرَوُا۟ ٱلْكُفْرَ بِٱلْإِيمَـٰنِ لَن يَضُرُّوا۟ ٱللَّهَ شَيْـًٔا وَلَهُمْ عَذَابٌ أَلِيمٌ

Transliteration inna alladhīna ish'tarawū l-kuf'ra bil-īmāni lan yaḍurrū l-laha shayan walahum ʿadhābun alīmun

Yoruba Dájúdájú àwọn tó fi ìgbàgbọ́ òdodo ra àìgbàgbọ́,wọn kò lè kó ìnira kan kan bá Allāhu. Ìyà ẹlẹ́ta-eléro sì wà fún wọn.

Verse 178

وَلَا يَحْسَبَنَّ ٱلَّذِينَ كَفَرُوٓا۟ أَنَّمَا نُمْلِى لَهُمْ خَيْرٌ لِّأَنفُسِهِمْ ۚ إِنَّمَا نُمْلِى لَهُمْ لِيَزْدَادُوٓا۟ إِثْمًا ۚ وَلَهُمْ عَذَابٌ مُّهِينٌ

Transliteration walā yaḥsabanna alladhīna kafarū annamā num'lī lahum khayrun li-anfusihim innamā num'lī lahum liyazdādū ith'man walahum ʿadhābun muhīnun

Yoruba Kí àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ má ṣe lérò pé bí A ṣe ń lọ́ra fún wọn jẹ́ oore fún wọn. A kàn ń lọ́ra fún wọn nítorí kí wọ́n lè lékún nínú ẹ̀ṣẹ̀ ni. Ìyà tí í yẹpẹrẹ ẹ̀dá sì wà fún wọn.

Verse 179

مَّا كَانَ ٱللَّهُ لِيَذَرَ ٱلْمُؤْمِنِينَ عَلَىٰ مَآ أَنتُمْ عَلَيْهِ حَتَّىٰ يَمِيزَ ٱلْخَبِيثَ مِنَ ٱلطَّيِّبِ ۗ وَمَا كَانَ ٱللَّهُ لِيُطْلِعَكُمْ عَلَى ٱلْغَيْبِ وَلَـٰكِنَّ ٱللَّهَ يَجْتَبِى مِن رُّسُلِهِۦ مَن يَشَآءُ ۖ فَـَٔامِنُوا۟ بِٱللَّهِ وَرُسُلِهِۦ ۚ وَإِن تُؤْمِنُوا۟ وَتَتَّقُوا۟ فَلَكُمْ أَجْرٌ عَظِيمٌ

Transliteration mā kāna l-lahu liyadhara l-mu'minīna ʿalā mā antum ʿalayhi ḥattā yamīza l-khabītha mina l-ṭayibi wamā kāna l-lahu liyuṭ'liʿakum ʿalā l-ghaybi walākinna l-laha yajtabī min rusulihi man yashāu faāminū bil-lahi warusulihi wa-in tu'minū watattaqū falakum ajrun ʿaẓīmun

Yoruba Allāhu kò níí gbé àwọn onígbàgbọ́ òdodo jù sílẹ̀ lórí ohun tí ẹ wà lórí rẹ̀ (níbi àìmọ onígbàgbọ́ òdodo lọ́tọ̀ yàtọ̀ sí ṣọ̀bẹ-ṣèlu) títí Ó máa fi ya ẹni burúkú sọ́tọ̀ kúrò lára ẹni dáadáa. Allāhu kò sì níí fi ìmọ̀ ìkọ̀kọ̀ mọ̀ yín, ṣùgbọ́n Allāhu yóò ṣẹ̀ṣà ẹni tí Ó bá fẹ́ nínú àwọn Òjíṣẹ́ Rẹ̀. Nítorí náà, ẹ gbàgbọ́ nínú Allāhu àti àwọn Òjíṣẹ́ Rẹ̀. Tí ẹ bá gbàgbọ́ ní òdodo, tí ẹ sì bẹ̀rù (Allāhu), ẹ̀san ńlá yó sì wà fún yín.

Verse 180

وَلَا يَحْسَبَنَّ ٱلَّذِينَ يَبْخَلُونَ بِمَآ ءَاتَىٰهُمُ ٱللَّهُ مِن فَضْلِهِۦ هُوَ خَيْرًا لَّهُم ۖ بَلْ هُوَ شَرٌّ لَّهُمْ ۖ سَيُطَوَّقُونَ مَا بَخِلُوا۟ بِهِۦ يَوْمَ ٱلْقِيَـٰمَةِ ۗ وَلِلَّهِ مِيرَٰثُ ٱلسَّمَـٰوَٰتِ وَٱلْأَرْضِ ۗ وَٱللَّهُ بِمَا تَعْمَلُونَ خَبِيرٌ

Transliteration walā yaḥsabanna alladhīna yabkhalūna bimā ātāhumu l-lahu min faḍlihi huwa khayran lahum bal huwa sharrun lahum sayuṭawwaqūna mā bakhilū bihi yawma l-qiyāmati walillahi mīrāthu l-samāwāti wal-arḍi wal-lahu bimā taʿmalūna khabīrun

Yoruba Kí àwọn tó ń ṣahun pẹ̀lú ohun tí Allāhu fún wọn nínú oore-àjùlọ Rẹ̀ má ṣe lérò pé oore ni fún wọn, bí kò ṣe pé aburú ni fún wọn. A ó fí ohun tí wọ́n fi ṣahun kọ́ wọn lọ́rùn ní Ọjọ́ Àjíǹde. Ti Allāhu sì ni ogún àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Allāhu sì ni Alámọ̀tán nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.

Verse 181

لَّقَدْ سَمِعَ ٱللَّهُ قَوْلَ ٱلَّذِينَ قَالُوٓا۟ إِنَّ ٱللَّهَ فَقِيرٌ وَنَحْنُ أَغْنِيَآءُ ۘ سَنَكْتُبُ مَا قَالُوا۟ وَقَتْلَهُمُ ٱلْأَنۢبِيَآءَ بِغَيْرِ حَقٍّ وَنَقُولُ ذُوقُوا۟ عَذَابَ ٱلْحَرِيقِ

Transliteration laqad samiʿa l-lahu qawla alladhīna qālū inna l-laha faqīrun wanaḥnu aghniyāu sanaktubu mā qālū waqatlahumu l-anbiyāa bighayri ḥaqqin wanaqūlu dhūqū ʿadhāba l-ḥarīqi

Yoruba Allāhu kúkú ti gbọ́ ọ̀rọ̀ àwọn tó wí pé: “Dájúdájú aláìní ni Allāhu, àwa sì ni ọlọ́rọ̀.” A máa ṣàkọsílẹ̀ ohun tí wọ́n wí àti pípa tí wọ́n pa àwọn Ànábì láì lẹ́tọ̀ọ́. A sì máa sọ pé: “Ẹ tọ́ ìyà Iná jónijóni wò.”

Verse 182

ذَٰلِكَ بِمَا قَدَّمَتْ أَيْدِيكُمْ وَأَنَّ ٱللَّهَ لَيْسَ بِظَلَّامٍ لِّلْعَبِيدِ

Transliteration dhālika bimā qaddamat aydīkum wa-anna l-laha laysa biẓallāmin lil'ʿabīdi

Yoruba Ìyẹn (rí bẹ́ẹ̀) nítorí ohun tí ọwọ́ yín tì síwájú. Àti pé dájúdájú Allāhu kò níí ṣe àbòsí fún àwọn ẹrú (Rẹ̀).

Verse 183

ٱلَّذِينَ قَالُوٓا۟ إِنَّ ٱللَّهَ عَهِدَ إِلَيْنَآ أَلَّا نُؤْمِنَ لِرَسُولٍ حَتَّىٰ يَأْتِيَنَا بِقُرْبَانٍ تَأْكُلُهُ ٱلنَّارُ ۗ قُلْ قَدْ جَآءَكُمْ رُسُلٌ مِّن قَبْلِى بِٱلْبَيِّنَـٰتِ وَبِٱلَّذِى قُلْتُمْ فَلِمَ قَتَلْتُمُوهُمْ إِن كُنتُمْ صَـٰدِقِينَ

Transliteration alladhīna qālū inna l-laha ʿahida ilaynā allā nu'mina lirasūlin ḥattā yatiyanā biqur'bānin takuluhu l-nāru qul qad jāakum rusulun min qablī bil-bayināti wabi-alladhī qul'tum falima qataltumūhum in kuntum ṣādiqīna

Yoruba Àwọn tó wí pé: “Dájúdájú Allāhu ṣàdéhùn fún wa pé a ò gbọdọ̀ gba Òjíṣẹ́ kan gbọ́ títí ó máa fí mú ẹran sàráà kan wá fún wa tí iná (àtọ̀runwá) yóò fi lánu.” Sọ pé: “Dájúdájú àwọn Òjíṣẹ́ kan ti wá ba yín ṣíwájú mi pẹ̀lú àwọn ẹ̀rí to yanjú àti èyí tí ẹ wí (yìí), nítorí kí ni ẹ fi pa wọ́n tí ẹ bá jẹ́ olódodo?”

Verse 184

فَإِن كَذَّبُوكَ فَقَدْ كُذِّبَ رُسُلٌ مِّن قَبْلِكَ جَآءُو بِٱلْبَيِّنَـٰتِ وَٱلزُّبُرِ وَٱلْكِتَـٰبِ ٱلْمُنِيرِ

Transliteration fa-in kadhabūka faqad kudhiba rusulun min qablika jāū bil-bayināti wal-zuburi wal-kitābi l-munīri

Yoruba Tí wọ́n bá pè ọ́ ní òpùrọ́, wọ́n kúkú ti pe àwọn Òjíṣẹ́ tó ṣíwájú rẹ ní òpùrọ́. Wọ́n wá pẹ̀lú àwọn ẹ̀rí tó yanjú, ìpín-ìpín Tírà àti Tírà tó ń tànmọ́lẹ̀ sí ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn.1

Verse 185

كُلُّ نَفْسٍ ذَآئِقَةُ ٱلْمَوْتِ ۗ وَإِنَّمَا تُوَفَّوْنَ أُجُورَكُمْ يَوْمَ ٱلْقِيَـٰمَةِ ۖ فَمَن زُحْزِحَ عَنِ ٱلنَّارِ وَأُدْخِلَ ٱلْجَنَّةَ فَقَدْ فَازَ ۗ وَمَا ٱلْحَيَوٰةُ ٱلدُّنْيَآ إِلَّا مَتَـٰعُ ٱلْغُرُورِ

Transliteration kullu nafsin dhāiqatu l-mawti wa-innamā tuwaffawna ujūrakum yawma l-qiyāmati faman zuḥ'ziḥa ʿani l-nāri wa-ud'khila l-janata faqad fāza wamā l-ḥayatu l-dun'yā illā matāʿu l-ghurūri

Yoruba Ẹ̀mí kọ̀ọ̀kan ló máa tọ́ ikú wò. A ó sì san yín ní ẹ̀san yín ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ní Ọjọ́ Àjíǹde. Nítorí náà, ẹnikẹ́ni tí A bá mú jìnnà tefé sí Iná, tí A sì mú wọ inú Ọgbà Ìdẹ̀ra, ó kúkú ti jèrè. Kí sì ni ìgbésí ayé bí kò ṣe ìgbádùn ẹ̀tàn.

Verse 186

۞ لَتُبْلَوُنَّ فِىٓ أَمْوَٰلِكُمْ وَأَنفُسِكُمْ وَلَتَسْمَعُنَّ مِنَ ٱلَّذِينَ أُوتُوا۟ ٱلْكِتَـٰبَ مِن قَبْلِكُمْ وَمِنَ ٱلَّذِينَ أَشْرَكُوٓا۟ أَذًى كَثِيرًا ۚ وَإِن تَصْبِرُوا۟ وَتَتَّقُوا۟ فَإِنَّ ذَٰلِكَ مِنْ عَزْمِ ٱلْأُمُورِ

Transliteration latub'lawunna fī amwālikum wa-anfusikum walatasmaʿunna mina alladhīna ūtū l-kitāba min qablikum wamina alladhīna ashrakū adhan kathīran wa-in taṣbirū watattaqū fa-inna dhālika min ʿazmi l-umūri

Yoruba Dájúdájú A ó máa dan yín wò nínú dúkìá yín àti ẹ̀mí yín. Dájúdájú ẹ̀yin yóò máa gbọ́ ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ọ̀rọ̀ ìpalára láti ọ̀dọ̀ àwọn tí A fún ní tírà ṣíwájú yín àti àwọn ọ̀ṣẹbọ. Tí ẹ̀yin bá ṣe sùúrù, tí ẹ sì bẹ̀rù (Allāhu), dájúdájú ìyẹn wà nínú àwọn ìpinnu ọ̀rọ̀ tó pọn dandan.

Verse 187

وَإِذْ أَخَذَ ٱللَّهُ مِيثَـٰقَ ٱلَّذِينَ أُوتُوا۟ ٱلْكِتَـٰبَ لَتُبَيِّنُنَّهُۥ لِلنَّاسِ وَلَا تَكْتُمُونَهُۥ فَنَبَذُوهُ وَرَآءَ ظُهُورِهِمْ وَٱشْتَرَوْا۟ بِهِۦ ثَمَنًا قَلِيلًا ۖ فَبِئْسَ مَا يَشْتَرُونَ

Transliteration wa-idh akhadha l-lahu mīthāqa alladhīna ūtū l-kitāba latubayyinunnahu lilnnāsi walā taktumūnahu fanabadhūhu warāa ẓuhūrihim wa-ish'taraw bihi thamanan qalīlan fabi'sa mā yashtarūna

Yoruba (Ẹ rántí) nígbà tí Allāhu gba àdéhùn àwọn tí A fún ní tírà pé ẹ gbọ́dọ̀ ṣe àlàyé rẹ̀ fún àwọn ènìyàn, ẹ ò sì gbọdọ̀ fi pamọ́. Wọ́n sì jù ú sẹ́yìn lẹ́yìn wọn. Wọ́n sì tà á ní owó kékeré. Nítorí náà, ohun tí wọ́n ń tà mà sì burú (níyà).

Verse 188

لَا تَحْسَبَنَّ ٱلَّذِينَ يَفْرَحُونَ بِمَآ أَتَوا۟ وَّيُحِبُّونَ أَن يُحْمَدُوا۟ بِمَا لَمْ يَفْعَلُوا۟ فَلَا تَحْسَبَنَّهُم بِمَفَازَةٍ مِّنَ ٱلْعَذَابِ ۖ وَلَهُمْ عَذَابٌ أَلِيمٌ

Transliteration lā taḥsabanna alladhīna yafraḥūna bimā ataw wayuḥibbūna an yuḥ'madū bimā lam yafʿalū falā taḥsabannahum bimafāzatin mina l-ʿadhābi walahum ʿadhābun alīmun

Yoruba Ẹ má ṣe lérò pé àwọn tó ń dunnú sí ohun tí wọ́n ṣe (ní àìdáa máa là nínú ìyà). Wọ́n sì nífẹ̀ẹ́ sí kí àwọn (ènìyàn) máa yìn wọ́n fún ohun tí wọn kò ṣe (níṣẹ́ rere). Nítorí náà, ẹ má ṣe rò wọ́n ro ìgbàlà níbi Ìyà. Ìyà ẹlẹ́ta eléro sì wà fún wọn.

Verse 189

وَلِلَّهِ مُلْكُ ٱلسَّمَـٰوَٰتِ وَٱلْأَرْضِ ۗ وَٱللَّهُ عَلَىٰ كُلِّ شَىْءٍ قَدِيرٌ

Transliteration walillahi mul'ku l-samāwāti wal-arḍi wal-lahu ʿalā kulli shayin qadīrun

Yoruba Ti Allāhu ni ìjọba àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Allāhu sì ni Alágbára lórí gbogbo n̄ǹkan.

Verse 190

إِنَّ فِى خَلْقِ ٱلسَّمَـٰوَٰتِ وَٱلْأَرْضِ وَٱخْتِلَـٰفِ ٱلَّيْلِ وَٱلنَّهَارِ لَـَٔايَـٰتٍ لِّأُو۟لِى ٱلْأَلْبَـٰبِ

Transliteration inna fī khalqi l-samāwāti wal-arḍi wa-ikh'tilāfi al-layli wal-nahāri laāyātin li-ulī l-albābi

Yoruba Dájúdájú àwọn àmì wà nínú ìṣẹ̀dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀, ìtẹ̀léǹtẹ̀lé òru àti ọ̀sán; (àmì wà nínú wọn) fún àwọn onílàákàyè.1

Verse 191

ٱلَّذِينَ يَذْكُرُونَ ٱللَّهَ قِيَـٰمًا وَقُعُودًا وَعَلَىٰ جُنُوبِهِمْ وَيَتَفَكَّرُونَ فِى خَلْقِ ٱلسَّمَـٰوَٰتِ وَٱلْأَرْضِ رَبَّنَا مَا خَلَقْتَ هَـٰذَا بَـٰطِلًا سُبْحَـٰنَكَ فَقِنَا عَذَابَ ٱلنَّارِ

Transliteration alladhīna yadhkurūna l-laha qiyāman waquʿūdan waʿalā junūbihim wayatafakkarūna fī khalqi l-samāwāti wal-arḍi rabbanā mā khalaqta hādhā bāṭilan sub'ḥānaka faqinā ʿadhāba l-nāri

Yoruba Àwọn tó ń rántí Allāhu ní ìnàró, ìjókòó àti ní ìdùbúlẹ̀; tí wọ́n ń ronú sí ìṣẹ̀dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀, (wọ́n sì ń sọ pé:) “Olúwa wa, Ìwọ kò ṣẹ̀dàá èyí pẹ̀lú irọ́. Mímọ́ ni fún Ọ. Nítorí náà, ṣọ́ wa níbi ìyà Iná.

Verse 192

رَبَّنَآ إِنَّكَ مَن تُدْخِلِ ٱلنَّارَ فَقَدْ أَخْزَيْتَهُۥ ۖ وَمَا لِلظَّـٰلِمِينَ مِنْ أَنصَارٍ

Transliteration rabbanā innaka man tud'khili l-nāra faqad akhzaytahu wamā lilẓẓālimīna min anṣārin

Yoruba Olúwa wa, dájúdájú ẹnikẹ́ni tí O bá mú wọ inú Iná, O ti dójú tì í. Kò sì níí sí àwọn olùrànlọ́wọ́ fún àwọn alábòsí.

Verse 193

رَّبَّنَآ إِنَّنَا سَمِعْنَا مُنَادِيًا يُنَادِى لِلْإِيمَـٰنِ أَنْ ءَامِنُوا۟ بِرَبِّكُمْ فَـَٔامَنَّا ۚ رَبَّنَا فَٱغْفِرْ لَنَا ذُنُوبَنَا وَكَفِّرْ عَنَّا سَيِّـَٔاتِنَا وَتَوَفَّنَا مَعَ ٱلْأَبْرَارِ

Transliteration rabbanā innanā samiʿ'nā munādiyan yunādī lil'īmāni an āminū birabbikum faāmannā rabbanā fa-igh'fir lanā dhunūbanā wakaffir ʿannā sayyiātinā watawaffanā maʿa l-abrāri

Yoruba Olúwa wa, dájúdájú àwa gbọ́ olùpèpè kan tó ń pe (ìpè) sí ibi ìgbàgbọ́ pé: “Ẹ gba Olúwa yín gbọ́.” A sì gbàgbọ́ ní òdodo. Olúwa wa, nítorí náà, forí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa jìn wá, kí O sì pa àwọn àṣìṣe wa rẹ́, kí O sì pa wá pẹ̀lú àwọn ẹni rere.

Verse 194

رَبَّنَا وَءَاتِنَا مَا وَعَدتَّنَا عَلَىٰ رُسُلِكَ وَلَا تُخْزِنَا يَوْمَ ٱلْقِيَـٰمَةِ ۗ إِنَّكَ لَا تُخْلِفُ ٱلْمِيعَادَ

Transliteration rabbanā waātinā mā waʿadttanā ʿalā rusulika walā tukh'zinā yawma l-qiyāmati innaka lā tukh'lifu l-mīʿāda

Yoruba Olúwa wa, fún wa ní ohun tí O ṣàdéhùn rẹ̀ fún wa lórí (ahọ́n) àwọn Òjíṣẹ́ Rẹ. Má sì ṣe dójú tì wá ní Ọjọ́ Àjíǹde. Dájúdájú Ìwọ kì í yapa àdéhùn.”

Verse 195

فَٱسْتَجَابَ لَهُمْ رَبُّهُمْ أَنِّى لَآ أُضِيعُ عَمَلَ عَـٰمِلٍ مِّنكُم مِّن ذَكَرٍ أَوْ أُنثَىٰ ۖ بَعْضُكُم مِّنۢ بَعْضٍ ۖ فَٱلَّذِينَ هَاجَرُوا۟ وَأُخْرِجُوا۟ مِن دِيَـٰرِهِمْ وَأُوذُوا۟ فِى سَبِيلِى وَقَـٰتَلُوا۟ وَقُتِلُوا۟ لَأُكَفِّرَنَّ عَنْهُمْ سَيِّـَٔاتِهِمْ وَلَأُدْخِلَنَّهُمْ جَنَّـٰتٍ تَجْرِى مِن تَحْتِهَا ٱلْأَنْهَـٰرُ ثَوَابًا مِّنْ عِندِ ٱللَّهِ ۗ وَٱللَّهُ عِندَهُۥ حُسْنُ ٱلثَّوَابِ

Transliteration fa-is'tajāba lahum rabbuhum annī lā uḍīʿu ʿamala ʿāmilin minkum min dhakarin aw unthā baʿḍukum min baʿḍin fa-alladhīna hājarū wa-ukh'rijū min diyārihim waūdhū fī sabīlī waqātalū waqutilū la-ukaffiranna ʿanhum sayyiātihim wala-ud'khilannahum jannātin tajrī min taḥtihā l-anhāru thawāban min ʿindi l-lahi wal-lahu ʿindahu ḥus'nu l-thawābi

Yoruba Olúwa wọn sì jẹ́pè wọn pé: “Dájúdájú Èmi kò níí fi iṣẹ́ oníṣẹ́ kan nínú yín ráre; ọkùnrin ni tàbí obìnrin, ara kan náà ni yín (níbi ẹ̀san). Nítorí náà, àwọn tó gbé (ìlú wọn) jù sílẹ̀, tí wọ́n lé jáde kúrò nínú ìlú wọn, tí wọ́n sì fi ìnira kàn wọ́n nítorí ẹ̀sìn Mi, wọ́n jagun ẹ̀sìn, wọ́n sì pa wọ́n, dájúdájú Èmi yóò bá wọn pa àwọn àṣìṣe wọn rẹ́, Èmi yó sì mú wọn wọ inú àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra tí àwọn odò ń ṣàn ní ìsàlẹ̀ rẹ̀. (Ó jẹ́) ẹ̀san láti ọ̀dọ̀ Allāhu. Ní ọ̀dọ̀ Allāhu sì ni ẹ̀san dáadáa wà.

Verse 196

لَا يَغُرَّنَّكَ تَقَلُّبُ ٱلَّذِينَ كَفَرُوا۟ فِى ٱلْبِلَـٰدِ

Transliteration lā yaghurrannaka taqallubu alladhīna kafarū fī l-bilādi

Yoruba Má ṣe gba ẹ̀tàn pẹ̀lú ìgbòkè-gbodò àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ nínú ìlú.

Verse 197

مَتَـٰعٌ قَلِيلٌ ثُمَّ مَأْوَىٰهُمْ جَهَنَّمُ ۚ وَبِئْسَ ٱلْمِهَادُ

Transliteration matāʿun qalīlun thumma mawāhum jahannamu wabi'sa l-mihādu

Yoruba Ìgbádùn díẹ̀ (lè wà fún wọn), lẹ́yìn náà iná Jahanamọ ni ibùgbé wọn. Ibùgbé náà sì burú.

Verse 198

لَـٰكِنِ ٱلَّذِينَ ٱتَّقَوْا۟ رَبَّهُمْ لَهُمْ جَنَّـٰتٌ تَجْرِى مِن تَحْتِهَا ٱلْأَنْهَـٰرُ خَـٰلِدِينَ فِيهَا نُزُلًا مِّنْ عِندِ ٱللَّهِ ۗ وَمَا عِندَ ٱللَّهِ خَيْرٌ لِّلْأَبْرَارِ

Transliteration lākini alladhīna ittaqaw rabbahum lahum jannātun tajrī min taḥtihā l-anhāru khālidīna fīhā nuzulan min ʿindi l-lahi wamā ʿinda l-lahi khayrun lil'abrāri

Yoruba Ṣùgbọ́n àwọn tó bẹ̀rù Olúwa wọn, àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra tí àwọn odò ń ṣàn ní ìsàlẹ̀ rẹ̀ ń bẹ fún wọn. Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀. Ibùdésí kan ni láti ọ̀dọ̀ Allāhu. Ohun tí ń bẹ lọ́dọ̀ Allāhu sì lóore jùlọ fún àwọn ẹni rere.

Verse 199

وَإِنَّ مِنْ أَهْلِ ٱلْكِتَـٰبِ لَمَن يُؤْمِنُ بِٱللَّهِ وَمَآ أُنزِلَ إِلَيْكُمْ وَمَآ أُنزِلَ إِلَيْهِمْ خَـٰشِعِينَ لِلَّهِ لَا يَشْتَرُونَ بِـَٔايَـٰتِ ٱللَّهِ ثَمَنًا قَلِيلًا ۗ أُو۟لَـٰٓئِكَ لَهُمْ أَجْرُهُمْ عِندَ رَبِّهِمْ ۗ إِنَّ ٱللَّهَ سَرِيعُ ٱلْحِسَابِ

Transliteration wa-inna min ahli l-kitābi laman yu'minu bil-lahi wamā unzila ilaykum wamā unzila ilayhim khāshiʿīna lillahi lā yashtarūna biāyāti l-lahi thamanan qalīlan ulāika lahum ajruhum ʿinda rabbihim inna l-laha sarīʿu l-ḥisābi

Yoruba Dájúdájú ó ń bẹ nínú àwọn onítírà ẹni tó gbàgbọ́ nínú Allāhu, àti ohun tí A sọ̀kalẹ̀ fún yín àti ohun tí A sọ̀kalẹ̀ fún wọn; wọ́n ń páyà Allāhu, wọn kì í ta àwọn ọ̀rọ̀ Allāhu ní owó kékeré. Àwọn wọ̀nyẹn ní ẹ̀san lọ́dọ̀ Olúwa wọn. Dájúdájú Allāhu ni Olùyára níbi ìṣírò-iṣẹ́.1

Verse 200

يَـٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُوا۟ ٱصْبِرُوا۟ وَصَابِرُوا۟ وَرَابِطُوا۟ وَٱتَّقُوا۟ ٱللَّهَ لَعَلَّكُمْ تُفْلِحُونَ

Transliteration yāayyuhā alladhīna āmanū iṣ'birū waṣābirū warābiṭū wa-ittaqū l-laha laʿallakum tuf'liḥūna

Yoruba Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ ṣe sùúrù, ẹ pàrọwà sùúrù, ẹ ṣọ́ bodè ìlú yín (láti lè dènà àwọn ọmọ-ogun ọ̀tá ẹ̀sìn). Kí ẹ sì bẹ̀rù Allāhu nítorí kí ẹ lè jèrè.

Read Surah Ali 'Imran in another language

All languages

All 114 surahs in Yoruba: the Qur’an in Yoruba.

Learn it in MyDugsi

Yoruba translation: Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni, from Quran.com. Transliteration: Quran.com. Recitation: Mishary Alafasy, from EveryAyah.com. MyDugsi is a learning aid, not a replacement for a qualified teacher.