MyDugsiStart learning

Surah Al-Mumtahanah in Yoruba: translation and audio

Surah 60 · الممتحنة · She that is to be examined · 13 verses

Surah Al-Mumtahanah verse by verse: the Arabic with a recitation you can repeat, the transliteration, and the Yoruba translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni. For the meaning of every word, see Surah Al-Mumtahanah word by word in English.

Verse 1

يَـٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُوا۟ لَا تَتَّخِذُوا۟ عَدُوِّى وَعَدُوَّكُمْ أَوْلِيَآءَ تُلْقُونَ إِلَيْهِم بِٱلْمَوَدَّةِ وَقَدْ كَفَرُوا۟ بِمَا جَآءَكُم مِّنَ ٱلْحَقِّ يُخْرِجُونَ ٱلرَّسُولَ وَإِيَّاكُمْ ۙ أَن تُؤْمِنُوا۟ بِٱللَّهِ رَبِّكُمْ إِن كُنتُمْ خَرَجْتُمْ جِهَـٰدًا فِى سَبِيلِى وَٱبْتِغَآءَ مَرْضَاتِى ۚ تُسِرُّونَ إِلَيْهِم بِٱلْمَوَدَّةِ وَأَنَا۠ أَعْلَمُ بِمَآ أَخْفَيْتُمْ وَمَآ أَعْلَنتُمْ ۚ وَمَن يَفْعَلْهُ مِنكُمْ فَقَدْ ضَلَّ سَوَآءَ ٱلسَّبِيلِ

Transliteration yāayyuhā alladhīna āmanū lā tattakhidhū ʿaduwwī waʿaduwwakum awliyāa tul'qūna ilayhim bil-mawadati waqad kafarū bimā jāakum mina l-ḥaqi yukh'rijūna l-rasūla wa-iyyākum an tu'minū bil-lahi rabbikum in kuntum kharajtum jihādan fī sabīlī wa-ib'tighāa marḍātī tusirrūna ilayhim bil-mawadati wa-anā aʿlamu bimā akhfaytum wamā aʿlantum waman yafʿalhu minkum faqad ḍalla sawāa l-sabīli

Yoruba Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ má ṣe mú ọ̀tá Mi àti ọ̀tá yín ní ọ̀rẹ́ tí ẹ óò máa fi ìfẹ́ hàn sí. Wọ́n kúkú ti ṣàì gbàgbọ́ nínú ohun tí ó dé ba yín nínú òdodo. Wọ́n yọ Òjíṣẹ́ àti ẹ̀yin náà kúrò nínú ìlú nítorí pé, ẹ gbàgbọ́ nínú Allāhu, Olúwa yín. Tí ẹ̀yin bá jáde fún ogun nítorí ẹ̀sìn Mi àti nítorí wíwá ìyọ́nú Mi, (ṣé) ẹ̀yin yóò tún máa ní ìfẹ́ kọ̀rọ̀ sí wọn ni! Èmi sì nímọ̀ jùlọ nípa ohun tí ẹ fi pamọ́ àti ohun tí ẹ fi hàn. Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe bẹ́ẹ̀ nínú yín, dájúdájú ó ti ṣìnà kúrò lójú ọ̀nà tààrà.

Verse 2

إِن يَثْقَفُوكُمْ يَكُونُوا۟ لَكُمْ أَعْدَآءً وَيَبْسُطُوٓا۟ إِلَيْكُمْ أَيْدِيَهُمْ وَأَلْسِنَتَهُم بِٱلسُّوٓءِ وَوَدُّوا۟ لَوْ تَكْفُرُونَ

Transliteration in yathqafūkum yakūnū lakum aʿdāan wayabsuṭū ilaykum aydiyahum wa-alsinatahum bil-sūi wawaddū law takfurūna

Yoruba Tí ọwọ́ wọn bá bà yín, wọ́n máa di ọ̀tá fún yín. Wọn yó sì fi ọwọ́ wọn àti ahọ́n wọn nawọ́ aburú si yín. Wọ́n sì máa fẹ́ kí ó jẹ́ pé ẹ di aláìgbàgbọ́.

Verse 3

لَن تَنفَعَكُمْ أَرْحَامُكُمْ وَلَآ أَوْلَـٰدُكُمْ ۚ يَوْمَ ٱلْقِيَـٰمَةِ يَفْصِلُ بَيْنَكُمْ ۚ وَٱللَّهُ بِمَا تَعْمَلُونَ بَصِيرٌ

Transliteration lan tanfaʿakum arḥāmukum walā awlādukum yawma l-qiyāmati yafṣilu baynakum wal-lahu bimā taʿmalūna baṣīrun

Yoruba Àwọn ẹbí yín àti àwọn ọmọ yín kò lè ṣe yín ní àǹfààní; ní Ọjọ́ Àjíǹde ni Allāhu máa ṣèpínyà láààrin yín. Allāhu sì ni Olùríran nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.

Verse 4

قَدْ كَانَتْ لَكُمْ أُسْوَةٌ حَسَنَةٌ فِىٓ إِبْرَٰهِيمَ وَٱلَّذِينَ مَعَهُۥٓ إِذْ قَالُوا۟ لِقَوْمِهِمْ إِنَّا بُرَءَٰٓؤُا۟ مِنكُمْ وَمِمَّا تَعْبُدُونَ مِن دُونِ ٱللَّهِ كَفَرْنَا بِكُمْ وَبَدَا بَيْنَنَا وَبَيْنَكُمُ ٱلْعَدَٰوَةُ وَٱلْبَغْضَآءُ أَبَدًا حَتَّىٰ تُؤْمِنُوا۟ بِٱللَّهِ وَحْدَهُۥٓ إِلَّا قَوْلَ إِبْرَٰهِيمَ لِأَبِيهِ لَأَسْتَغْفِرَنَّ لَكَ وَمَآ أَمْلِكُ لَكَ مِنَ ٱللَّهِ مِن شَىْءٍ ۖ رَّبَّنَا عَلَيْكَ تَوَكَّلْنَا وَإِلَيْكَ أَنَبْنَا وَإِلَيْكَ ٱلْمَصِيرُ

Transliteration qad kānat lakum us'watun ḥasanatun fī ib'rāhīma wa-alladhīna maʿahu idh qālū liqawmihim innā buraāu minkum wamimmā taʿbudūna min dūni l-lahi kafarnā bikum wabadā baynanā wabaynakumu l-ʿadāwatu wal-baghḍāu abadan ḥattā tu'minū bil-lahi waḥdahu illā qawla ib'rāhīma li-abīhi la-astaghfiranna laka wamā amliku laka mina l-lahi min shayin rabbanā ʿalayka tawakkalnā wa-ilayka anabnā wa-ilayka l-maṣīru

Yoruba Dájúdájú àwòkọ́ṣe rere ti wà fún yín ní ara (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm àti àwọn tó wà pẹ̀lú rẹ̀. Nígbà tí wọ́n sọ fún ìjọ wọn pé: "Dájúdájú àwa yọwọ́-yọsẹ̀ kúrò nínú ọ̀rọ̀ yín àti ohun tí ẹ̀ ń jọ́sìn fún lẹ́yìn Allāhu. A takò yín. Ọ̀tá àti ìkórira sì ti hàn láààrin wa títí láéláé àyàfi ìgbà tí ẹ bá tó gbàgbọ́ nínú Allāhu nìkan ṣoṣo. - Àfi ọ̀rọ̀ tí (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm sọ fún bàbá rẹ̀ pé: “Dájúdájú mo máa tọrọ àforíjìn fún ọ, èmi kò sì ní ìkápá kiní kan fún ọ lọ́dọ̀ Allāhu. - Olúwa wa, Ìwọ l’a gbáralé. Ọ̀dọ̀ Rẹ l’a ṣẹ́rí padà sí (nípa ìronúpìwàdà). Ọ̀dọ̀ Rẹ sì ni àbọ̀ ẹ̀dá.

Verse 5

رَبَّنَا لَا تَجْعَلْنَا فِتْنَةً لِّلَّذِينَ كَفَرُوا۟ وَٱغْفِرْ لَنَا رَبَّنَآ ۖ إِنَّكَ أَنتَ ٱلْعَزِيزُ ٱلْحَكِيمُ

Transliteration rabbanā lā tajʿalnā fit'natan lilladhīna kafarū wa-igh'fir lanā rabbanā innaka anta l-ʿazīzu l-ḥakīmu

Yoruba Olúwa wa, má ṣe wá ní àdánwò fún àwọn tó ṣàì gbàgbọ́.Foríjìn wá, Olúwa wa. Dájúdájú Ìwọ ni Alágbára, Ọlọ́gbọ́n.”

Verse 6

لَقَدْ كَانَ لَكُمْ فِيهِمْ أُسْوَةٌ حَسَنَةٌ لِّمَن كَانَ يَرْجُوا۟ ٱللَّهَ وَٱلْيَوْمَ ٱلْـَٔاخِرَ ۚ وَمَن يَتَوَلَّ فَإِنَّ ٱللَّهَ هُوَ ٱلْغَنِىُّ ٱلْحَمِيدُ

Transliteration laqad kāna lakum fīhim us'watun ḥasanatun liman kāna yarjū l-laha wal-yawma l-ākhira waman yatawalla fa-inna l-laha huwa l-ghaniyu l-ḥamīdu

Yoruba Dájúdájú àwòkọ́ṣe rere ti wà fún yín ní ara wọn fún ẹni tó ń retí (ẹ̀sán) Allāhu àti Ọjọ́ Ìkẹ́yìn. Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbúnrí, dájúdájú Allāhu, Òun ni Ọlọ́rọ̀, Ẹlẹ́yìn.

Verse 7

۞ عَسَى ٱللَّهُ أَن يَجْعَلَ بَيْنَكُمْ وَبَيْنَ ٱلَّذِينَ عَادَيْتُم مِّنْهُم مَّوَدَّةً ۚ وَٱللَّهُ قَدِيرٌ ۚ وَٱللَّهُ غَفُورٌ رَّحِيمٌ

Transliteration ʿasā l-lahu an yajʿala baynakum wabayna alladhīna ʿādaytum min'hum mawaddatan wal-lahu qadīrun wal-lahu ghafūrun raḥīmun

Yoruba Ó lè jẹ́ pé Allāhu yóò fi ìfẹ́ sí ààrin ẹ̀yin àti àwọn tí ẹ mú ní ọ̀tá nínú wọn (ìyẹn, nígbà tí wọ́n bá di mùsùlùmí). Allāhu ni Alágbára. Allāhu sì ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.

Verse 8

لَّا يَنْهَىٰكُمُ ٱللَّهُ عَنِ ٱلَّذِينَ لَمْ يُقَـٰتِلُوكُمْ فِى ٱلدِّينِ وَلَمْ يُخْرِجُوكُم مِّن دِيَـٰرِكُمْ أَن تَبَرُّوهُمْ وَتُقْسِطُوٓا۟ إِلَيْهِمْ ۚ إِنَّ ٱللَّهَ يُحِبُّ ٱلْمُقْسِطِينَ

Transliteration lā yanhākumu l-lahu ʿani alladhīna lam yuqātilūkum fī l-dīni walam yukh'rijūkum min diyārikum an tabarrūhum watuq'siṭū ilayhim inna l-laha yuḥibbu l-muq'siṭīna

Yoruba Allāhu kò kọ̀ fún yín nípa àwọn tí kò gbé ogun tì yín nípa ẹ̀sìn, tí wọn kò sì lè yín jáde kúrò nínú ìlú yín, pé kí ẹ ṣe dáadáa sí wọn, kí ẹ sì ṣe déédé sí wọn. Dájúdájú Allāhu fẹ́ràn àwọn olùṣe-déédé.

Verse 9

إِنَّمَا يَنْهَىٰكُمُ ٱللَّهُ عَنِ ٱلَّذِينَ قَـٰتَلُوكُمْ فِى ٱلدِّينِ وَأَخْرَجُوكُم مِّن دِيَـٰرِكُمْ وَظَـٰهَرُوا۟ عَلَىٰٓ إِخْرَاجِكُمْ أَن تَوَلَّوْهُمْ ۚ وَمَن يَتَوَلَّهُمْ فَأُو۟لَـٰٓئِكَ هُمُ ٱلظَّـٰلِمُونَ

Transliteration innamā yanhākumu l-lahu ʿani alladhīna qātalūkum fī l-dīni wa-akhrajūkum min diyārikum waẓāharū ʿalā ikh'rājikum an tawallawhum waman yatawallahum fa-ulāika humu l-ẓālimūna

Yoruba Ohun tí Allāhu kọ̀ fún yín nípa àwọn tó gbógun tì yín nínú ẹ̀sìn, tí wọ́n sì lè yín jáde kúrò nínú ìlú yín, tí wọ́n tún ṣe ìrànlọ́wọ́ (fún àwọn ọ̀tá yín) láti le yín jáde, ni pé (Ó kọ̀ fún yín) láti mú wọn ní ọ̀rẹ́. Ẹnikẹ́ni tí ó bá mú wọn ní ọ̀rẹ́, àwọn wọ̀nyẹn gan-an ni alábòsí.

Verse 10

يَـٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُوٓا۟ إِذَا جَآءَكُمُ ٱلْمُؤْمِنَـٰتُ مُهَـٰجِرَٰتٍ فَٱمْتَحِنُوهُنَّ ۖ ٱللَّهُ أَعْلَمُ بِإِيمَـٰنِهِنَّ ۖ فَإِنْ عَلِمْتُمُوهُنَّ مُؤْمِنَـٰتٍ فَلَا تَرْجِعُوهُنَّ إِلَى ٱلْكُفَّارِ ۖ لَا هُنَّ حِلٌّ لَّهُمْ وَلَا هُمْ يَحِلُّونَ لَهُنَّ ۖ وَءَاتُوهُم مَّآ أَنفَقُوا۟ ۚ وَلَا جُنَاحَ عَلَيْكُمْ أَن تَنكِحُوهُنَّ إِذَآ ءَاتَيْتُمُوهُنَّ أُجُورَهُنَّ ۚ وَلَا تُمْسِكُوا۟ بِعِصَمِ ٱلْكَوَافِرِ وَسْـَٔلُوا۟ مَآ أَنفَقْتُمْ وَلْيَسْـَٔلُوا۟ مَآ أَنفَقُوا۟ ۚ ذَٰلِكُمْ حُكْمُ ٱللَّهِ ۖ يَحْكُمُ بَيْنَكُمْ ۚ وَٱللَّهُ عَلِيمٌ حَكِيمٌ

Transliteration yāayyuhā alladhīna āmanū idhā jāakumu l-mu'minātu muhājirātin fa-im'taḥinūhunna l-lahu aʿlamu biīmānihinna fa-in ʿalim'tumūhunna mu'minātin falā tarjiʿūhunna ilā l-kufāri lā hunna ḥillun lahum walā hum yaḥillūna lahunna waātūhum mā anfaqū walā junāḥa ʿalaykum an tankiḥūhunna idhā ātaytumūhunna ujūrahunna walā tum'sikū biʿiṣami l-kawāfiri wasalū mā anfaqtum walyasalū mā anfaqū dhālikum ḥuk'mu l-lahi yaḥkumu baynakum wal-lahu ʿalīmun ḥakīmun

Yoruba Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, nígbà tí àwọn onígbàgbọ́ òdodo lóbìnrin bá wá ba yín, tí wọ́n gbé ìlú àwọn aláìgbàgbọ́ jù sílẹ̀ fún ààbò ẹ̀sìn wọn, ẹ ṣe ìdánwò fún wọn. Allāhu nímọ̀ jùlọ nípa ìgbàgbọ́ wọn. Nítorí náà, tí ẹ bá mọ̀ wọ́n sí onígbàgbọ́ òdodo, ẹ má ṣe dá wọn padà sí ọ̀dọ̀ àwọn aláìgbàgbọ́. Àwọn onígbàgbọ́ òdodo lóbìnrin kò lẹ́tọ̀ọ́ sí wọn. Àwọn aláìgbàgbọ́ lọ́kùnrin kò sì lẹ́tọ̀ọ́ sí wọn.Ẹ fún (àwọn aláìgbàgbọ́ lọ́kùnrin) ní owó tí wọ́n ná (ní owó-orí obìnrin náà). Kò sì sí ẹ̀ṣẹ̀ fún ẹ̀yin náà pé kí ẹ fẹ́ wọn nígbà tí ẹ bá ti fún (àwọn obìnrin wọ̀nyí) ní owó-orí wọn. Ẹ má ṣe fi owó-orí àwọn obìnrin yín tí wọ́n jẹ́ aláìgbàgbọ́ mú wọn mọ́lẹ̀ (gẹ́gẹ́ bí ìyàwó yín láì jẹ́ pé wọ́n gba ’Islām pẹ̀lú yín).2 Ẹ bèèrè ohun tí ẹ ná (ní owó-orí wọn lọ́wọ́ aláìgbàgbọ́ lọ́kùnrin tí wọ́n sá lọ bá). Kí àwọn (aláìgbàgbọ́ lọ́kùnrin náà) bèèrè ohun tí àwọn náà ná (ní owó-orí wọn lọ́wọ́ ẹ̀yin tí onígbàgbọ́ òdodo lóbìnrin sá wá bá). Ìyẹn ni ìdájọ́ Allāhu. Ó sì ń dájọ́ láààrin yín. Allāhu sì ni Onímọ̀, Ọlọ́gbọ́n.

Verse 11

وَإِن فَاتَكُمْ شَىْءٌ مِّنْ أَزْوَٰجِكُمْ إِلَى ٱلْكُفَّارِ فَعَاقَبْتُمْ فَـَٔاتُوا۟ ٱلَّذِينَ ذَهَبَتْ أَزْوَٰجُهُم مِّثْلَ مَآ أَنفَقُوا۟ ۚ وَٱتَّقُوا۟ ٱللَّهَ ٱلَّذِىٓ أَنتُم بِهِۦ مُؤْمِنُونَ

Transliteration wa-in fātakum shayon min azwājikum ilā l-kufāri faʿāqabtum faātū alladhīna dhahabat azwājuhum mith'la mā anfaqū wa-ittaqū l-laha alladhī antum bihi mu'minūna

Yoruba Tí kiní kan láti ọ̀dọ̀ àwọn ìyàwó yín bá bọ́ mọ yín lọ́wọ́ sí ọ̀dọ̀ àwọn aláìgbàgbọ́, tí ẹ sì kórè ogun, ẹ fún àwọn tí ìyàwó wọn sá lọ ní irú òdiwọ̀n ohun tí wọ́n ná (ní owó-orí). Kí ẹ sì bẹ̀rù Allāhu, Ẹni tí ẹ̀yin ní ìgbàgbọ́ òdodo nínú Rẹ̀.

Verse 12

يَـٰٓأَيُّهَا ٱلنَّبِىُّ إِذَا جَآءَكَ ٱلْمُؤْمِنَـٰتُ يُبَايِعْنَكَ عَلَىٰٓ أَن لَّا يُشْرِكْنَ بِٱللَّهِ شَيْـًٔا وَلَا يَسْرِقْنَ وَلَا يَزْنِينَ وَلَا يَقْتُلْنَ أَوْلَـٰدَهُنَّ وَلَا يَأْتِينَ بِبُهْتَـٰنٍ يَفْتَرِينَهُۥ بَيْنَ أَيْدِيهِنَّ وَأَرْجُلِهِنَّ وَلَا يَعْصِينَكَ فِى مَعْرُوفٍ ۙ فَبَايِعْهُنَّ وَٱسْتَغْفِرْ لَهُنَّ ٱللَّهَ ۖ إِنَّ ٱللَّهَ غَفُورٌ رَّحِيمٌ

Transliteration yāayyuhā l-nabiyu idhā jāaka l-mu'minātu yubāyiʿ'naka ʿalā an lā yush'rik'na bil-lahi shayan walā yasriq'na walā yaznīna walā yaqtul'na awlādahunna walā yatīna bibuh'tānin yaftarīnahu bayna aydīhinna wa-arjulihinna walā yaʿṣīnaka fī maʿrūfin fabāyiʿ'hunna wa-is'taghfir lahunna l-laha inna l-laha ghafūrun raḥīmun

Yoruba Ìwọ Ànábì, nígbà tí àwọn onígbàgbọ́ òdodo lóbìnrin bá wá bá ọ, tí wọ́n ń ṣe àdéhùn fún ọ pé àwọn kò níí fi kiní kan ṣẹbọ sí Allāhu, àwọn kò níí jalè, àwọn kò níí ṣe sìná, àwọn kò níí pa ọmọ wọn, àwọn kò níí mú àdápa irọ́ wá, àdápa irọ́ tí wọ́n ń mú wá láààrin ọwọ́ wọn àti ẹsẹ̀ wọn (ìyẹn ni gbígbé oyún olóyún fún ọkọ wọn), àwọn kò sì níí yapa rẹ níbi n̄ǹkan dáadáa, nígbà náà bá wọn ṣe àdéhùn, kí ó sì bá wọn tọrọ àforíjìn lọ́dọ̀ Allāhu. Dájúdájú Allāhu ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.

Verse 13

يَـٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُوا۟ لَا تَتَوَلَّوْا۟ قَوْمًا غَضِبَ ٱللَّهُ عَلَيْهِمْ قَدْ يَئِسُوا۟ مِنَ ٱلْـَٔاخِرَةِ كَمَا يَئِسَ ٱلْكُفَّارُ مِنْ أَصْحَـٰبِ ٱلْقُبُورِ

Transliteration yāayyuhā alladhīna āmanū lā tatawallaw qawman ghaḍiba l-lahu ʿalayhim qad ya-isū mina l-ākhirati kamā ya-isa l-kufāru min aṣḥābi l-qubūri

Yoruba Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ má ṣe mú ìjọ kan tí Allāhu ti bínú sí ní ọ̀rẹ́. Dájúdájú wọ́n ti sọ̀rètí nù nípa ọ̀run, gẹ́gẹ́ bí àwọn aláìgbàgbọ́ tó wà nínú sàréè (ṣe sọ̀rètí nù nípa ìkẹ́).

Read Surah Al-Mumtahanah in another language

All languages

All 114 surahs in Yoruba: the Qur’an in Yoruba.

Learn it in MyDugsi

Yoruba translation: Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni, from Quran.com. Transliteration: Quran.com. Recitation: Mishary Alafasy, from EveryAyah.com. MyDugsi is a learning aid, not a replacement for a qualified teacher.