Surah Al-Kahf in Yoruba: translation and audio
Surah 18 · الكهف · The Cave · 110 verses
Surah Al-Kahf verse by verse: the Arabic with a recitation you can repeat, the transliteration, and the Yoruba translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni. For the meaning of every word, see Surah Al-Kahf word by word in English.
Verse 1
ٱلْحَمْدُ لِلَّهِ ٱلَّذِىٓ أَنزَلَ عَلَىٰ عَبْدِهِ ٱلْكِتَـٰبَ وَلَمْ يَجْعَل لَّهُۥ عِوَجَا ۜ
Transliteration al-ḥamdu lillahi alladhī anzala ʿalā ʿabdihi l-kitāba walam yajʿal lahu ʿiwajā
Yoruba Gbogbo ẹyìn ń jẹ́ ti Allāhu, Ẹni tí Ó sọ Tírà kalẹ̀ fún ẹrúsìn Rẹ̀. Kò sì dojú ọ̀rọ̀ kan rú nínú rẹ̀.
Verse 2
قَيِّمًا لِّيُنذِرَ بَأْسًا شَدِيدًا مِّن لَّدُنْهُ وَيُبَشِّرَ ٱلْمُؤْمِنِينَ ٱلَّذِينَ يَعْمَلُونَ ٱلصَّـٰلِحَـٰتِ أَنَّ لَهُمْ أَجْرًا حَسَنًا
Transliteration qayyiman liyundhira basan shadīdan min ladun'hu wayubashira l-mu'minīna alladhīna yaʿmalūna l-ṣāliḥāti anna lahum ajran ḥasanan
Yoruba (Ó ṣe é ni tírà) tó dúró déédénítorí kí (Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -) lè fi ṣe ìkìlọ̀ ìyà líle láti ọ̀dọ̀ (Allāhu) àti nítorí kí ó lè fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo, àwọn tó ń ṣe iṣẹ́ rere ní ìró ìdùnnú pé dájúdájú ẹ̀san rere ń bẹ fún wọn (nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra);
Verse 3
مَّـٰكِثِينَ فِيهِ أَبَدًا
Transliteration mākithīna fīhi abadan
Yoruba Wọn yóò máa gbé nínú rẹ̀ lọ títí láéláé.
Verse 4
وَيُنذِرَ ٱلَّذِينَ قَالُوا۟ ٱتَّخَذَ ٱللَّهُ وَلَدًا
Transliteration wayundhira alladhīna qālū ittakhadha l-lahu waladan
Yoruba Àti nítorí kí ó lè ṣe ìkìlọ̀ fún àwọn tó wí pé: “Allāhu mú ẹnì kan ní ọmọ.”
Verse 5
مَّا لَهُم بِهِۦ مِنْ عِلْمٍ وَلَا لِـَٔابَآئِهِمْ ۚ كَبُرَتْ كَلِمَةً تَخْرُجُ مِنْ أَفْوَٰهِهِمْ ۚ إِن يَقُولُونَ إِلَّا كَذِبًا
Transliteration mā lahum bihi min ʿil'min walā liābāihim kaburat kalimatan takhruju min afwāhihim in yaqūlūna illā kadhiban
Yoruba Kò sí ìmọ̀ kan kan fún àwọn àti bàbá wọn nípa rẹ̀. Ọ̀rọ̀ tó ń jáde lẹ́nu wọn tóbi. Dájúdájú wọn kò wí kiní kan bí kò ṣe irọ́.
Verse 6
فَلَعَلَّكَ بَـٰخِعٌ نَّفْسَكَ عَلَىٰٓ ءَاثَـٰرِهِمْ إِن لَّمْ يُؤْمِنُوا۟ بِهَـٰذَا ٱلْحَدِيثِ أَسَفًا
Transliteration falaʿallaka bākhiʿun nafsaka ʿalā āthārihim in lam yu'minū bihādhā l-ḥadīthi asafan
Yoruba Nítorí náà, nítorí kí ni o ṣe máa fi ìbànújẹ́ para rẹ lórí ìgbésẹ̀ wọn pé wọn kò gba ọ̀rọ̀ (al-Ƙur’ān) yìí gbọ́.
Verse 7
إِنَّا جَعَلْنَا مَا عَلَى ٱلْأَرْضِ زِينَةً لَّهَا لِنَبْلُوَهُمْ أَيُّهُمْ أَحْسَنُ عَمَلًا
Transliteration innā jaʿalnā mā ʿalā l-arḍi zīnatan lahā linabluwahum ayyuhum aḥsanu ʿamalan
Yoruba Dájúdájú Àwa ṣe ohun tí ń bẹ lórí ilẹ̀ ní ọ̀ṣọ́ fún ará-ayé nítorí kí Á lè dán wọn wò (pé) èwo nínú wọn ló máa dára jùlọ níbi iṣẹ́ ṣíṣe (nínú ẹ̀sìn).
Verse 8
وَإِنَّا لَجَـٰعِلُونَ مَا عَلَيْهَا صَعِيدًا جُرُزًا
Transliteration wa-innā lajāʿilūna mā ʿalayhā ṣaʿīdan juruzan
Yoruba Àti pé dájúdájú Àwa máa sọ n̄ǹkan tí ń bẹ lórí (ilẹ̀) di erùpẹ̀ gbígbẹ tí kò níí hu irúgbìn.
Verse 9
أَمْ حَسِبْتَ أَنَّ أَصْحَـٰبَ ٱلْكَهْفِ وَٱلرَّقِيمِ كَانُوا۟ مِنْ ءَايَـٰتِنَا عَجَبًا
Transliteration am ḥasib'ta anna aṣḥāba l-kahfi wal-raqīmi kānū min āyātinā ʿajaban
Yoruba Tàbí o lérò pé dájúdájú àwọn ará inú ọ̀gbun àpáta àti wàláhà orúkọ wọn jẹ́ èèmọ̀ kan nínú àwọn àmì Wa?
Verse 10
إِذْ أَوَى ٱلْفِتْيَةُ إِلَى ٱلْكَهْفِ فَقَالُوا۟ رَبَّنَآ ءَاتِنَا مِن لَّدُنكَ رَحْمَةً وَهَيِّئْ لَنَا مِنْ أَمْرِنَا رَشَدًا
Transliteration idh awā l-fit'yatu ilā l-kahfi faqālū rabbanā ātinā min ladunka raḥmatan wahayyi lanā min amrinā rashadan
Yoruba (Rántí) nígbà tí àwọn ọ̀dọ́kùnrin náà wá ibùgbé sínú ọ̀gbun àpáta, wọ́n sọ pé: “Olúwa wa, fún wa ní ìkẹ́ láti ọ̀dọ̀ Rẹ, kí O ṣe ìmọ̀nà ní ìrọ̀rùn fún wa nínú ọ̀rọ̀ wa.”
Verse 11
فَضَرَبْنَا عَلَىٰٓ ءَاذَانِهِمْ فِى ٱلْكَهْفِ سِنِينَ عَدَدًا
Transliteration faḍarabnā ʿalā ādhānihim fī l-kahfi sinīna ʿadadan
Yoruba A kùn wọ́n l’óorun àsùnpiyè nínú ọ̀gbun àpáta f’ọ́dún gbọọrọ.
Verse 12
ثُمَّ بَعَثْنَـٰهُمْ لِنَعْلَمَ أَىُّ ٱلْحِزْبَيْنِ أَحْصَىٰ لِمَا لَبِثُوٓا۟ أَمَدًا
Transliteration thumma baʿathnāhum linaʿlama ayyu l-ḥiz'bayni aḥṣā limā labithū amadan
Yoruba Lẹ́yìn náà, A gbé wọn dìde nítorí kí Á lè ṣàfi hàn èwo nínú ìjọ méjèèjì ló mọ gbèdéke òǹkà ọdún tó lò (nínú ọ̀gbun àpáta náà).
Verse 13
نَّحْنُ نَقُصُّ عَلَيْكَ نَبَأَهُم بِٱلْحَقِّ ۚ إِنَّهُمْ فِتْيَةٌ ءَامَنُوا۟ بِرَبِّهِمْ وَزِدْنَـٰهُمْ هُدًى
Transliteration naḥnu naquṣṣu ʿalayka naba-ahum bil-ḥaqi innahum fit'yatun āmanū birabbihim wazid'nāhum hudan
Yoruba Àwa ń sọ ìròyìn wọn fún ọ pẹ̀lú òdodo. Dájúdájú ọ̀dọ́kùnrin ni wọ́n. Wọ́n gbàgbọ́ nínú Olúwa wọn. A sì ṣàlékún ìmọ̀nà fún wọn.
Verse 14
وَرَبَطْنَا عَلَىٰ قُلُوبِهِمْ إِذْ قَامُوا۟ فَقَالُوا۟ رَبُّنَا رَبُّ ٱلسَّمَـٰوَٰتِ وَٱلْأَرْضِ لَن نَّدْعُوَا۟ مِن دُونِهِۦٓ إِلَـٰهًا ۖ لَّقَدْ قُلْنَآ إِذًا شَطَطًا
Transliteration warabaṭnā ʿalā qulūbihim idh qāmū faqālū rabbunā rabbu l-samāwāti wal-arḍi lan nadʿuwā min dūnihi ilāhan laqad qul'nā idhan shaṭaṭan
Yoruba A sì kì wọ́n lọ́kàn nígbà tí wọ́n dìde, tí wọ́n sọ pé: “Olúwa wa ni Olúwa àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. A ò sì níí pe ọlọ́hun kan lẹ́yìn Rẹ̀. (Tí a bá pe ọlọ́hun kan lẹ́yìn Rẹ̀) dájúdájú nígbà náà a ti sọ̀rọ̀ tó tayọ ẹnu-ààlà.
Verse 15
هَـٰٓؤُلَآءِ قَوْمُنَا ٱتَّخَذُوا۟ مِن دُونِهِۦٓ ءَالِهَةً ۖ لَّوْلَا يَأْتُونَ عَلَيْهِم بِسُلْطَـٰنٍۭ بَيِّنٍ ۖ فَمَنْ أَظْلَمُ مِمَّنِ ٱفْتَرَىٰ عَلَى ٱللَّهِ كَذِبًا
Transliteration hāulāi qawmunā ittakhadhū min dūnihi ālihatan lawlā yatūna ʿalayhim bisul'ṭānin bayyinin faman aẓlamu mimmani if'tarā ʿalā l-lahi kadhiban
Yoruba Àwọn ìjọ wa wọ̀nyí sọ àwọn kan di ọlọ́hun lẹ́yìn Allāhu. Kí ni kò jẹ́ kí wọ́n mú ẹ̀rí tó yanjú wá nípa wọn? Nítorí náà, ta ni ó ṣe àbòsí ju ẹni tó dá àdápa irọ́ mọ́ Allāhu?”
Verse 16
وَإِذِ ٱعْتَزَلْتُمُوهُمْ وَمَا يَعْبُدُونَ إِلَّا ٱللَّهَ فَأْوُۥٓا۟ إِلَى ٱلْكَهْفِ يَنشُرْ لَكُمْ رَبُّكُم مِّن رَّحْمَتِهِۦ وَيُهَيِّئْ لَكُم مِّنْ أَمْرِكُم مِّرْفَقًا
Transliteration wa-idhi iʿ'tazaltumūhum wamā yaʿbudūna illā l-laha fawū ilā l-kahfi yanshur lakum rabbukum min raḥmatihi wayuhayyi lakum min amrikum mir'faqan
Yoruba (Rántí nígbà tí àwọn ọ̀dọ́kùnrin náà sọ fúnra wọn pé:) nígbà tí ẹ bá yẹra fún àwọn àti n̄ǹkan tí wọ́n ń jọ́sìn fún lẹ́yìn Allāhu, kí ẹ wá ibùgbé sínú ọ̀gbun àpáta, Olúwa yín yóò tẹ́ nínú ìkẹ́ Rẹ̀ sílẹ̀ fún yín. Ó sì máa ṣe ọ̀rọ̀ yín ní ìrọ̀rùn fún yín.
Verse 17
۞ وَتَرَى ٱلشَّمْسَ إِذَا طَلَعَت تَّزَٰوَرُ عَن كَهْفِهِمْ ذَاتَ ٱلْيَمِينِ وَإِذَا غَرَبَت تَّقْرِضُهُمْ ذَاتَ ٱلشِّمَالِ وَهُمْ فِى فَجْوَةٍ مِّنْهُ ۚ ذَٰلِكَ مِنْ ءَايَـٰتِ ٱللَّهِ ۗ مَن يَهْدِ ٱللَّهُ فَهُوَ ٱلْمُهْتَدِ ۖ وَمَن يُضْلِلْ فَلَن تَجِدَ لَهُۥ وَلِيًّا مُّرْشِدًا
Transliteration watarā l-shamsa idhā ṭalaʿat tazāwaru ʿan kahfihim dhāta l-yamīni wa-idhā gharabat taqriḍuhum dhāta l-shimāli wahum fī fajwatin min'hu dhālika min āyāti l-lahi man yahdi l-lahu fahuwa l-muh'tadi waman yuḍ'lil falan tajida lahu waliyyan mur'shidan
Yoruba O máa rí òòrùn nígbà tí ó bá yọ, ó máa yẹ̀bá kúrò níbi ọ̀gbun wọn sí ọwọ́ ọ̀tún. Nígbà tí ó bá tún wọ̀, ó máa fi wọ́n sílẹ̀ sí ọwọ́ òsì. Wọ́n sì wà nínú àyè tí ó fẹjú nínú ọ̀gbun àpáta. Ìyẹn wà nínú àwọn àmì Allāhu. Ẹnikẹ́ni tí Allāhu bá fi mọ̀nà (’Islām), òun ni olùmọ̀nà. Ẹnikẹ́ni tí Ó bá ṣì lọ́nà, o ò sì níí rí olùrànlọ́wọ́ atọ́ni-sọ́nà kan fún un.
Verse 18
وَتَحْسَبُهُمْ أَيْقَاظًا وَهُمْ رُقُودٌ ۚ وَنُقَلِّبُهُمْ ذَاتَ ٱلْيَمِينِ وَذَاتَ ٱلشِّمَالِ ۖ وَكَلْبُهُم بَـٰسِطٌ ذِرَاعَيْهِ بِٱلْوَصِيدِ ۚ لَوِ ٱطَّلَعْتَ عَلَيْهِمْ لَوَلَّيْتَ مِنْهُمْ فِرَارًا وَلَمُلِئْتَ مِنْهُمْ رُعْبًا
Transliteration wataḥsabuhum ayqāẓan wahum ruqūdun wanuqallibuhum dhāta l-yamīni wadhāta l-shimāli wakalbuhum bāsiṭun dhirāʿayhi bil-waṣīdi lawi iṭṭalaʿta ʿalayhim lawallayta min'hum firāran walamuli'ta min'hum ruʿ'ban
Yoruba (Tí o bá rí wọn), ó máa lérò pé wọ́n kò sí lójú oorun, ojú oorun ni wọ́n sì wà. A sì ń yí wọn ní ẹ̀gbẹ́ padà sí ọ̀tún àti sí òsì. Ajá wọn sì na apá rẹ̀ méjèèjì sílẹ̀ ní ẹnu-ọ̀nà. Tí ó bá jẹ́ pé o yọjú wò wọ́n ni, ìwọ ìbá pẹ̀yìndà láti họ fún wọn, ìwọ ìbá sì kún fún ìbẹ̀rù-bojo láti ara wọn.
Verse 19
وَكَذَٰلِكَ بَعَثْنَـٰهُمْ لِيَتَسَآءَلُوا۟ بَيْنَهُمْ ۚ قَالَ قَآئِلٌ مِّنْهُمْ كَمْ لَبِثْتُمْ ۖ قَالُوا۟ لَبِثْنَا يَوْمًا أَوْ بَعْضَ يَوْمٍ ۚ قَالُوا۟ رَبُّكُمْ أَعْلَمُ بِمَا لَبِثْتُمْ فَٱبْعَثُوٓا۟ أَحَدَكُم بِوَرِقِكُمْ هَـٰذِهِۦٓ إِلَى ٱلْمَدِينَةِ فَلْيَنظُرْ أَيُّهَآ أَزْكَىٰ طَعَامًا فَلْيَأْتِكُم بِرِزْقٍ مِّنْهُ وَلْيَتَلَطَّفْ وَلَا يُشْعِرَنَّ بِكُمْ أَحَدًا
Transliteration wakadhālika baʿathnāhum liyatasāalū baynahum qāla qāilun min'hum kam labith'tum qālū labith'nā yawman aw baʿḍa yawmin qālū rabbukum aʿlamu bimā labith'tum fa-ib'ʿathū aḥadakum biwariqikum hādhihi ilā l-madīnati falyanẓur ayyuhā azkā ṭaʿāman falyatikum biriz'qin min'hu walyatalaṭṭaf walā yush'ʿiranna bikum aḥadan
Yoruba Báyẹn (ni wọ́n wà) tí A fi gbé wọn dìde padà nítorí kí wọ́n lè bi ara wọn léèrè ìbéèrè. Òǹsọ̀rọ̀ kan nínú wọn sọ pé: “Ìgbà wo lẹ ti wà níbí?” Wọ́n sọ pé: “A wà níbí fún ọjọ́ kan tàbí apá kan nínú ọjọ́.” Wọ́n sọ pé: “Olúwa yín lÓ nímọ̀ jùlọ nípa ìgbà tí ẹ ti wà níbí.” Nítorí náà, ẹ gbé ọ̀kan nínú yín dìde lọ sí inú ìlú pẹ̀lú owó fàdákà yín yìí. Kí ó wo èwó nínú oúnjẹ ìlú ló mọ́ jùlọ, kí ó sì mú àsè wá fún yín nínú rẹ̀. Kí ó ṣe pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́, kò sì gbọdọ̀ jẹ́ kí ẹnì kan kan fura si yín.
Verse 20
إِنَّهُمْ إِن يَظْهَرُوا۟ عَلَيْكُمْ يَرْجُمُوكُمْ أَوْ يُعِيدُوكُمْ فِى مِلَّتِهِمْ وَلَن تُفْلِحُوٓا۟ إِذًا أَبَدًا
Transliteration innahum in yaẓharū ʿalaykum yarjumūkum aw yuʿīdūkum fī millatihim walan tuf'liḥū idhan abadan
Yoruba (Nítorí pé) dájúdájú tí wọ́n bá fi lè mọ̀ nípa yín, wọn yóò jù yín lókò tàbí kí wọ́n da yín padà sínú ẹ̀sìn wọn. (Tí ó bá sì fi rí bẹ́ẹ̀) nígbà náà, ẹ kò níí jèrè mọ́ láéláé.
Verse 21
وَكَذَٰلِكَ أَعْثَرْنَا عَلَيْهِمْ لِيَعْلَمُوٓا۟ أَنَّ وَعْدَ ٱللَّهِ حَقٌّ وَأَنَّ ٱلسَّاعَةَ لَا رَيْبَ فِيهَآ إِذْ يَتَنَـٰزَعُونَ بَيْنَهُمْ أَمْرَهُمْ ۖ فَقَالُوا۟ ٱبْنُوا۟ عَلَيْهِم بُنْيَـٰنًا ۖ رَّبُّهُمْ أَعْلَمُ بِهِمْ ۚ قَالَ ٱلَّذِينَ غَلَبُوا۟ عَلَىٰٓ أَمْرِهِمْ لَنَتَّخِذَنَّ عَلَيْهِم مَّسْجِدًا
Transliteration wakadhālika aʿtharnā ʿalayhim liyaʿlamū anna waʿda l-lahi ḥaqqun wa-anna l-sāʿata lā rayba fīhā idh yatanāzaʿūna baynahum amrahum faqālū ib'nū ʿalayhim bun'yānan rabbuhum aʿlamu bihim qāla alladhīna ghalabū ʿalā amrihim lanattakhidhanna ʿalayhim masjidan
Yoruba Báyẹn ni A ṣe jẹ́ kí àwọn ènìyàn rí wọn nítorí kí wọ́n lè mọ̀ pé dájúdájú àdéhùn Allāhu ni òdodo. Àti pé dájúdájú Àkókò náà kò sí iyèméjì nínú rẹ̀. Rántí (nígbà tí àwọn ènìyàn) ń ṣe àríyànjiyàn láààrin ara wọn nípa ọ̀rọ̀ wọn. Wọ́n sọ pé: “Ẹ mọ ilé kan lé wọn lórí. Olúwa wọn lÓ nímọ̀ jùlọ nípa wọn.” Àwọn tó borí lórí ọ̀rọ̀ wọn sì wí pé: “Dájúdájú a máa sọ orí àpáta wọn di mọ́sálásí.”1
Verse 22
سَيَقُولُونَ ثَلَـٰثَةٌ رَّابِعُهُمْ كَلْبُهُمْ وَيَقُولُونَ خَمْسَةٌ سَادِسُهُمْ كَلْبُهُمْ رَجْمًۢا بِٱلْغَيْبِ ۖ وَيَقُولُونَ سَبْعَةٌ وَثَامِنُهُمْ كَلْبُهُمْ ۚ قُل رَّبِّىٓ أَعْلَمُ بِعِدَّتِهِم مَّا يَعْلَمُهُمْ إِلَّا قَلِيلٌ ۗ فَلَا تُمَارِ فِيهِمْ إِلَّا مِرَآءً ظَـٰهِرًا وَلَا تَسْتَفْتِ فِيهِم مِّنْهُمْ أَحَدًا
Transliteration sayaqūlūna thalāthatun rābiʿuhum kalbuhum wayaqūlūna khamsatun sādisuhum kalbuhum rajman bil-ghaybi wayaqūlūna sabʿatun wathāminuhum kalbuhum qul rabbī aʿlamu biʿiddatihim mā yaʿlamuhum illā qalīlun falā tumāri fīhim illā mirāan ẓāhiran walā tastafti fīhim min'hum aḥadan
Yoruba Wọ́n ń wí pé: “Mẹ́ta ni wọ́n. Ajá wọn ṣe ìkẹrin wọn.” Wọ́n tún ń wí pé: “Márùn-ún ni wọ́n. Ajá wọn ṣe ìkẹfà wọn.” Ọ̀rọ̀ tó pamọ́ fún wọn ni wọ́n ń sọ, (wọ́n ń dá àbá ni). Wọ́n tún ń wí pé: “Méje ni wọ́n. Ajá wọn ṣe ìkẹjọ wọn.” Sọ pé: “Olúwa mi lÓ nímọ̀ jùlọ nípa òǹkà wọn. Kò sí (ẹni tí) ó mọ (òǹkà) wọn àfi àwọn díẹ̀. Nítorí náà, má ṣe bá wọn ṣe àríyànjiyàn nípa (òǹkà) wọn àfi (kí o fi) àríyànjiyàn (náà tì síbi ẹ̀rí) tó yanjú (tí A sọ̀kalẹ̀ fún ọ yìí). Má sì ṣe bi ẹnì kan nínú wọn léèrè nípa (òǹkà) wọn.”
Verse 23
وَلَا تَقُولَنَّ لِشَا۟ىْءٍ إِنِّى فَاعِلٌ ذَٰلِكَ غَدًا
Transliteration walā taqūlanna lishāy'in innī fāʿilun dhālika ghadan
Yoruba Má ṣe sọ nípa kiní kan pé: “Dájúdájú èmi yóò ṣe ìyẹn ní ọ̀la.”
Verse 24
إِلَّآ أَن يَشَآءَ ٱللَّهُ ۚ وَٱذْكُر رَّبَّكَ إِذَا نَسِيتَ وَقُلْ عَسَىٰٓ أَن يَهْدِيَنِ رَبِّى لِأَقْرَبَ مِنْ هَـٰذَا رَشَدًا
Transliteration illā an yashāa l-lahu wa-udh'kur rabbaka idhā nasīta waqul ʿasā an yahdiyani rabbī li-aqraba min hādhā rashadan
Yoruba Àyàfi (kí o fi kún un pé) “tí Allāhu bá fẹ́.” Ṣe ìrántí Olúwa rẹ nígbà tí o bá gbàgbé (láti sọ bẹ́ẹ̀ lásìkò náà). Kí o sì sọ (fún wọn) pé: “Ó rọrùn kí Olúwa mi tọ́ mi sọ́nà lórí rẹ̀ pẹ̀lú èyí tí ó súnmọ́ jù èyí lọ ní ìmọ̀nà (fún yín).”1
Verse 25
وَلَبِثُوا۟ فِى كَهْفِهِمْ ثَلَـٰثَ مِا۟ئَةٍ سِنِينَ وَٱزْدَادُوا۟ تِسْعًا
Transliteration walabithū fī kahfihim thalātha mi-atin sinīna wa-iz'dādū tis'ʿan
Yoruba Wọ́n wà nínú ọ̀gbun àpáta wọn fún ọ̀ọ́dúnrún ọdún. Wọ́n tún lo àlékún ọdún mẹ́sàn-án.
Verse 26
قُلِ ٱللَّهُ أَعْلَمُ بِمَا لَبِثُوا۟ ۖ لَهُۥ غَيْبُ ٱلسَّمَـٰوَٰتِ وَٱلْأَرْضِ ۖ أَبْصِرْ بِهِۦ وَأَسْمِعْ ۚ مَا لَهُم مِّن دُونِهِۦ مِن وَلِىٍّ وَلَا يُشْرِكُ فِى حُكْمِهِۦٓ أَحَدًا
Transliteration quli l-lahu aʿlamu bimā labithū lahu ghaybu l-samāwāti wal-arḍi abṣir bihi wa-asmiʿ mā lahum min dūnihi min waliyyin walā yush'riku fī ḥuk'mihi aḥadan
Yoruba Sọ pé: “Allāhu lÓ nímọ̀ jùlọ nípa ohun tí wọ́n lò (nínú ọ̀gbun àpáta). TiRẹ̀ ni ìkọ̀kọ̀ àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Kì ni kò rí tán, kì sí ni kò gbọ́ tán! Kò sí aláàbò kan fún wọn lẹ́yìn Rẹ̀. Kò sì fi ẹnì kan ṣe akẹgbẹ́ nínú ìdájọ́ Rẹ̀.”
Verse 27
وَٱتْلُ مَآ أُوحِىَ إِلَيْكَ مِن كِتَابِ رَبِّكَ ۖ لَا مُبَدِّلَ لِكَلِمَـٰتِهِۦ وَلَن تَجِدَ مِن دُونِهِۦ مُلْتَحَدًا
Transliteration wa-ut'lu mā ūḥiya ilayka min kitābi rabbika lā mubaddila likalimātihi walan tajida min dūnihi mul'taḥadan
Yoruba Ké ohun tí A fi ránṣẹ́ sí ọ nínú Tírà Olúwa rẹ. Kò sí ẹni tí ó lè yí àwọn ọ̀rọ̀ Rẹ̀ padà. Ìwọ kò sì lè rí ibùsásí kan lẹ́yìn ọ̀dọ̀ Rẹ̀.
Verse 28
وَٱصْبِرْ نَفْسَكَ مَعَ ٱلَّذِينَ يَدْعُونَ رَبَّهُم بِٱلْغَدَوٰةِ وَٱلْعَشِىِّ يُرِيدُونَ وَجْهَهُۥ ۖ وَلَا تَعْدُ عَيْنَاكَ عَنْهُمْ تُرِيدُ زِينَةَ ٱلْحَيَوٰةِ ٱلدُّنْيَا ۖ وَلَا تُطِعْ مَنْ أَغْفَلْنَا قَلْبَهُۥ عَن ذِكْرِنَا وَٱتَّبَعَ هَوَىٰهُ وَكَانَ أَمْرُهُۥ فُرُطًا
Transliteration wa-iṣ'bir nafsaka maʿa alladhīna yadʿūna rabbahum bil-ghadati wal-ʿashiyi yurīdūna wajhahu walā taʿdu ʿaynāka ʿanhum turīdu zīnata l-ḥayati l-dun'yā walā tuṭiʿ man aghfalnā qalbahu ʿan dhik'rinā wa-ittabaʿa hawāhu wakāna amruhu furuṭan
Yoruba Ṣe sùúrù fún ẹ̀mí rẹ láti wà pẹ̀lú àwọn tó ń pe Olúwa wọn ní òwúrọ̀ àti ní àṣálẹ́, tí wọ́n ń wá Ojú rere Rẹ̀. Má ṣe fojú pa wọ́n rẹ́ láti wá ọ̀ṣọ́ ìṣẹ̀mí ayé (yìí). Má sì ṣe tẹ̀lé ẹni tí A mú ọkàn rẹ̀ gbàgbé ìrántí Wa. Ó tẹ̀lé ìfẹ́-inú rẹ̀; ọ̀rọ̀ rẹ̀ sì jẹ́ àṣejù.1
Verse 29
وَقُلِ ٱلْحَقُّ مِن رَّبِّكُمْ ۖ فَمَن شَآءَ فَلْيُؤْمِن وَمَن شَآءَ فَلْيَكْفُرْ ۚ إِنَّآ أَعْتَدْنَا لِلظَّـٰلِمِينَ نَارًا أَحَاطَ بِهِمْ سُرَادِقُهَا ۚ وَإِن يَسْتَغِيثُوا۟ يُغَاثُوا۟ بِمَآءٍ كَٱلْمُهْلِ يَشْوِى ٱلْوُجُوهَ ۚ بِئْسَ ٱلشَّرَابُ وَسَآءَتْ مُرْتَفَقًا
Transliteration waquli l-ḥaqu min rabbikum faman shāa falyu'min waman shāa falyakfur innā aʿtadnā lilẓẓālimīna nāran aḥāṭa bihim surādiquhā wa-in yastaghīthū yughāthū bimāin kal-muh'li yashwī l-wujūha bi'sa l-sharābu wasāat mur'tafaqan
Yoruba Sọ pé: “Òdodo (nìyí) láti ọ̀dọ̀ Olúwa yín. Nítorí náà, ẹni tí ó bá fẹ́ kí ó gbàgbọ́ ní òdodo. Ẹni tí ó bá sì fẹ́ kí ó ṣàì gbàgbọ́. Dájúdájú Àwa pèsè Iná sílẹ̀ de àwọn alábòsí, tí ọgbà rẹ̀ yóò yí wọn po. Tí wọ́n bá ń tọrọ omi mímu, A óò fún wọn ní omi mímu kan tó dà bí ògéré epo gbígbóná, tí (ìgbóná rẹ̀) yó sì máa ṣe àwọn ojú. Ohun mímu náà burú. Ó sì burú ní ibùkójọ.
Verse 30
إِنَّ ٱلَّذِينَ ءَامَنُوا۟ وَعَمِلُوا۟ ٱلصَّـٰلِحَـٰتِ إِنَّا لَا نُضِيعُ أَجْرَ مَنْ أَحْسَنَ عَمَلًا
Transliteration inna alladhīna āmanū waʿamilū l-ṣāliḥāti innā lā nuḍīʿu ajra man aḥsana ʿamalan
Yoruba Dájúdájú àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe àwọn iṣẹ́ rere, dájúdájú Àwa kò níí fi ẹ̀san ẹni tí ó bá ṣe iṣẹ́ rere ráre.
Verse 31
أُو۟لَـٰٓئِكَ لَهُمْ جَنَّـٰتُ عَدْنٍ تَجْرِى مِن تَحْتِهِمُ ٱلْأَنْهَـٰرُ يُحَلَّوْنَ فِيهَا مِنْ أَسَاوِرَ مِن ذَهَبٍ وَيَلْبَسُونَ ثِيَابًا خُضْرًا مِّن سُندُسٍ وَإِسْتَبْرَقٍ مُّتَّكِـِٔينَ فِيهَا عَلَى ٱلْأَرَآئِكِ ۚ نِعْمَ ٱلثَّوَابُ وَحَسُنَتْ مُرْتَفَقًا
Transliteration ulāika lahum jannātu ʿadnin tajrī min taḥtihimu l-anhāru yuḥallawna fīhā min asāwira min dhahabin wayalbasūna thiyāban khuḍ'ran min sundusin wa-is'tabraqin muttakiīna fīhā ʿalā l-arāiki niʿ'ma l-thawābu waḥasunat mur'tafaqan
Yoruba Àwọn wọ̀nyẹn, tiwọn ni àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra ‘Adn, tí àwọn odò yóò máa ṣàn ní ìsàlẹ̀ wọn. Wọn máa ṣe wọ́n ní ọ̀ṣọ́ nínú rẹ̀ pẹ̀lú àwọn n̄ǹkan ọwọ́ látara wúrà. Wọn yóò máa wọ aṣọ àrán aláwọ̀ ewéko (èyí tí ó) fẹ́lẹ́ àti (èyí tí) ó nípọn. Wọn yó sì máa rọ̀gbọ̀kú lórí ibùsùn ọlá nínú (Ọgbà Ìdẹ̀ra). Ẹ̀san náà dára. Ó sì dára ní ibùkójọ.
Verse 32
۞ وَٱضْرِبْ لَهُم مَّثَلًا رَّجُلَيْنِ جَعَلْنَا لِأَحَدِهِمَا جَنَّتَيْنِ مِنْ أَعْنَـٰبٍ وَحَفَفْنَـٰهُمَا بِنَخْلٍ وَجَعَلْنَا بَيْنَهُمَا زَرْعًا
Transliteration wa-iḍ'rib lahum mathalan rajulayni jaʿalnā li-aḥadihimā jannatayni min aʿnābin waḥafafnāhumā binakhlin wajaʿalnā baynahumā zarʿan
Yoruba Fi àwọn ọkùnrin méjì kan ṣe àpẹ̀ẹrẹ fún wọn; A fún ọ̀kan nínú wọn ní ọgbà èso àjàrà méjì. A sì fi àwọn igi dàbínù yí wọn ká. A tún fi àwọn igi eléso là wọ́n láààrin.
Verse 33
كِلْتَا ٱلْجَنَّتَيْنِ ءَاتَتْ أُكُلَهَا وَلَمْ تَظْلِم مِّنْهُ شَيْـًٔا ۚ وَفَجَّرْنَا خِلَـٰلَهُمَا نَهَرًا
Transliteration kil'tā l-janatayni ātat ukulahā walam taẓlim min'hu shayan wafajjarnā khilālahumā naharan
Yoruba Ìkíní kejì àwọn oko méjèèjì ń so èso wọn. Àwọn èso rẹ̀ kì í pẹ̀ dín. A sì jẹ́ kí odò ṣàn kọjá láààrin oko méjèèjì.
Verse 34
وَكَانَ لَهُۥ ثَمَرٌ فَقَالَ لِصَـٰحِبِهِۦ وَهُوَ يُحَاوِرُهُۥٓ أَنَا۠ أَكْثَرُ مِنكَ مَالًا وَأَعَزُّ نَفَرًا
Transliteration wakāna lahu thamarun faqāla liṣāḥibihi wahuwa yuḥāwiruhu anā aktharu minka mālan wa-aʿazzu nafaran
Yoruba Ó ní èso (sẹ́). Ó sì sọ fún ọ̀rẹ́ rẹ̀ nígbà tí ó ń bá a jiyàn (báyìí) pé: “Èmi ní dúkìá lọ́wọ́ jù ọ́ lọ. Mo tún fi àwọn ènìyàn ní agbára jù ọ́ lọ.”
Verse 35
وَدَخَلَ جَنَّتَهُۥ وَهُوَ ظَالِمٌ لِّنَفْسِهِۦ قَالَ مَآ أَظُنُّ أَن تَبِيدَ هَـٰذِهِۦٓ أَبَدًا
Transliteration wadakhala jannatahu wahuwa ẓālimun linafsihi qāla mā aẓunnu an tabīda hādhihi abadan
Yoruba Ó wọ inú oko rẹ̀ ní ẹni tí ó ń ṣàbòsí sí ẹ̀mí ara rẹ̀, ó wí pé: “Èmi kò lérò pé èyí máa parun láéláé.
Verse 36
وَمَآ أَظُنُّ ٱلسَّاعَةَ قَآئِمَةً وَلَئِن رُّدِدتُّ إِلَىٰ رَبِّى لَأَجِدَنَّ خَيْرًا مِّنْهَا مُنقَلَبًا
Transliteration wamā aẓunnu l-sāʿata qāimatan wala-in rudidttu ilā rabbī la-ajidanna khayran min'hā munqalaban
Yoruba Èmi kò sì lérò pé Àkókò náà máa ṣẹlẹ̀. Àti pé tí wọ́n bá tiẹ̀ dá mi padà sí ọ̀dọ̀ Olúwa mi, dájúdájú mo tún máa rí ibùdésí tó dára ju èyí lọ.”
Verse 37
قَالَ لَهُۥ صَاحِبُهُۥ وَهُوَ يُحَاوِرُهُۥٓ أَكَفَرْتَ بِٱلَّذِى خَلَقَكَ مِن تُرَابٍ ثُمَّ مِن نُّطْفَةٍ ثُمَّ سَوَّىٰكَ رَجُلًا
Transliteration qāla lahu ṣāḥibuhu wahuwa yuḥāwiruhu akafarta bi-alladhī khalaqaka min turābin thumma min nuṭ'fatin thumma sawwāka rajulan
Yoruba Ọ̀rẹ́ rẹ̀ sọ fún un nígbà tí ó ń jà á níyàn (báyìí) pé: “Ṣé o máa ṣàì gbàgbọ́ nínú Ẹni tí Ó ṣẹ̀dá rẹ láti inú erùpẹ̀, lẹ́yìn náà, láti inú àtọ̀. Lẹ́yìn náà, Ó ṣe ọ́ ní ọkùnrin tó pé ní ẹ̀dá.
Verse 38
لَّـٰكِنَّا۠ هُوَ ٱللَّهُ رَبِّى وَلَآ أُشْرِكُ بِرَبِّىٓ أَحَدًا
Transliteration lākinnā huwa l-lahu rabbī walā ush'riku birabbī aḥadan
Yoruba Ṣùgbọ́n ní tèmi, Olúwa mi, Òun ni Allāhu. Èmi kò sì níí sọ ẹnì kan di akẹgbẹ́ fún Olúwa mi.
Verse 39
وَلَوْلَآ إِذْ دَخَلْتَ جَنَّتَكَ قُلْتَ مَا شَآءَ ٱللَّهُ لَا قُوَّةَ إِلَّا بِٱللَّهِ ۚ إِن تَرَنِ أَنَا۠ أَقَلَّ مِنكَ مَالًا وَوَلَدًا
Transliteration walawlā idh dakhalta jannataka qul'ta mā shāa l-lahu lā quwwata illā bil-lahi in tarani anā aqalla minka mālan wawaladan
Yoruba Nígbà tí o wọ inú ọgbà oko rẹ, kí ni kò mú ọ sọ pé: “Ohun tí Allāhu bá fẹ́! Kò sí agbára kan bí kò ṣe pẹ̀lú ìyọ̀ǹda Allāhu. Tí o bá sì rí èmi pé mo kéré sí ọ ní dúkìá àti ọmọ,
Verse 40
فَعَسَىٰ رَبِّىٓ أَن يُؤْتِيَنِ خَيْرًا مِّن جَنَّتِكَ وَيُرْسِلَ عَلَيْهَا حُسْبَانًا مِّنَ ٱلسَّمَآءِ فَتُصْبِحَ صَعِيدًا زَلَقًا
Transliteration faʿasā rabbī an yu'tiyani khayran min jannatika wayur'sila ʿalayhā ḥus'bānan mina l-samāi fatuṣ'biḥa ṣaʿīdan zalaqan
Yoruba ó súnmọ́ kí Olúwa mi fún èmi náà ní oore kan tí ó máa dára ju ọgbà oko tìrẹ. (Ó sì súnmọ́) kí Ó sọ ìyà kan kalẹ̀ sínú ọgbà oko rẹ láti sánmọ̀; ó sì máa di ilẹ̀ aṣálẹ̀.
Verse 41
أَوْ يُصْبِحَ مَآؤُهَا غَوْرًا فَلَن تَسْتَطِيعَ لَهُۥ طَلَبًا
Transliteration aw yuṣ'biḥa māuhā ghawran falan tastaṭīʿa lahu ṭalaban
Yoruba Tàbí kí omi rẹ̀ gbẹ. O ò sì níí lè wá omi kàn.”
Verse 42
وَأُحِيطَ بِثَمَرِهِۦ فَأَصْبَحَ يُقَلِّبُ كَفَّيْهِ عَلَىٰ مَآ أَنفَقَ فِيهَا وَهِىَ خَاوِيَةٌ عَلَىٰ عُرُوشِهَا وَيَقُولُ يَـٰلَيْتَنِى لَمْ أُشْرِكْ بِرَبِّىٓ أَحَدًا
Transliteration wa-uḥīṭa bithamarihi fa-aṣbaḥa yuqallibu kaffayhi ʿalā mā anfaqa fīhā wahiya khāwiyatun ʿalā ʿurūshihā wayaqūlu yālaytanī lam ush'rik birabbī aḥadan
Yoruba Wọ́n sì pa èso rẹ̀ run pátápátá. Ó sì di ẹni tó ń fí ọwọ́ rẹ̀ méjèèjì lura wọn pẹ́ẹ́pẹ́nípa ohun tí ó ti ná sórí rẹ̀. (Àwọn ilé rẹ̀) dàwó lulẹ̀ tòrùlé-tòrùlé wọn. Ó sì ń wí pé: “Yéè! Èmi ìbá tí sọ ẹnì kan kan di akẹgbẹ́ fún Olúwa mi. (Èmi ìbá má ṣẹbọ)”
Verse 43
وَلَمْ تَكُن لَّهُۥ فِئَةٌ يَنصُرُونَهُۥ مِن دُونِ ٱللَّهِ وَمَا كَانَ مُنتَصِرًا
Transliteration walam takun lahu fi-atun yanṣurūnahu min dūni l-lahi wamā kāna muntaṣiran
Yoruba Kò ní ìjọ kan tí ó máa ràn án lọ́wọ́ mọ́ lẹ́yìn Allāhu. Kò sì lè ran ara rẹ̀ lọ́wọ́.
Verse 44
هُنَالِكَ ٱلْوَلَـٰيَةُ لِلَّهِ ٱلْحَقِّ ۚ هُوَ خَيْرٌ ثَوَابًا وَخَيْرٌ عُقْبًا
Transliteration hunālika l-walāyatu lillahi l-ḥaqi huwa khayrun thawāban wakhayrun ʿuq'ban
Yoruba Níbẹ̀ yẹn, ti Allāhu, Ọba Òdodo ni ìjọba. Ó lóore jùlọ ní ẹ̀san, Ó sì lóore jùlọ ní ìkángun (rere).
Verse 45
وَٱضْرِبْ لَهُم مَّثَلَ ٱلْحَيَوٰةِ ٱلدُّنْيَا كَمَآءٍ أَنزَلْنَـٰهُ مِنَ ٱلسَّمَآءِ فَٱخْتَلَطَ بِهِۦ نَبَاتُ ٱلْأَرْضِ فَأَصْبَحَ هَشِيمًا تَذْرُوهُ ٱلرِّيَـٰحُ ۗ وَكَانَ ٱللَّهُ عَلَىٰ كُلِّ شَىْءٍ مُّقْتَدِرًا
Transliteration wa-iḍ'rib lahum mathala l-ḥayati l-dun'yā kamāin anzalnāhu mina l-samāi fa-ikh'talaṭa bihi nabātu l-arḍi fa-aṣbaḥa hashīman tadhrūhu l-riyāḥu wakāna l-lahu ʿalā kulli shayin muq'tadiran
Yoruba Ṣe àkàwé ilé ayé fún wọn; ó dà bí omi tí A sọ̀kalẹ̀ láti sánmọ̀. Lẹ́yìn náà, ó ròpọ̀ mọ́ irúgbìn ilẹ̀. Lẹ́yìn náà, (irúgbìn) di gbígbẹ, tí atẹ́gùn ń fọ́nká. Allāhu sì ń jẹ́ Alágbára lórí gbogbo n̄ǹkan.
Verse 46
ٱلْمَالُ وَٱلْبَنُونَ زِينَةُ ٱلْحَيَوٰةِ ٱلدُّنْيَا ۖ وَٱلْبَـٰقِيَـٰتُ ٱلصَّـٰلِحَـٰتُ خَيْرٌ عِندَ رَبِّكَ ثَوَابًا وَخَيْرٌ أَمَلًا
Transliteration al-mālu wal-banūna zīnatu l-ḥayati l-dun'yā wal-bāqiyātu l-ṣāliḥātu khayrun ʿinda rabbika thawāban wakhayrun amalan
Yoruba Ọ̀ṣọ́ ìṣẹ̀mí ayé ni dúkìá àti àwọn ọmọ. Àwọn iṣẹ́ rere tó máa wà títí láéláé lóore jùlọ ní ẹ̀san lọ́dọ̀ Olúwa rẹ, ó sì lóore jùlọ ní ìrètí.
Verse 47
وَيَوْمَ نُسَيِّرُ ٱلْجِبَالَ وَتَرَى ٱلْأَرْضَ بَارِزَةً وَحَشَرْنَـٰهُمْ فَلَمْ نُغَادِرْ مِنْهُمْ أَحَدًا
Transliteration wayawma nusayyiru l-jibāla watarā l-arḍa bārizatan waḥasharnāhum falam nughādir min'hum aḥadan
Yoruba (Rántí) ọjọ́ tí A máa mú àwọn àpáta rìn (kúrò ní àyè wọn). O sì máa rí ilẹ̀ tí ó máa fojú hàn (tí kò níí sí n̄ǹkan kan mọ́ lórí rẹ̀). A máa kó wọn jọ. A ò sì níí fi ẹnì kan sílẹ̀ nínú wọn.
Verse 48
وَعُرِضُوا۟ عَلَىٰ رَبِّكَ صَفًّا لَّقَدْ جِئْتُمُونَا كَمَا خَلَقْنَـٰكُمْ أَوَّلَ مَرَّةٍۭ ۚ بَلْ زَعَمْتُمْ أَلَّن نَّجْعَلَ لَكُم مَّوْعِدًا
Transliteration waʿuriḍū ʿalā rabbika ṣaffan laqad ji'tumūnā kamā khalaqnākum awwala marratin bal zaʿamtum allan najʿala lakum mawʿidan
Yoruba Wọn yó sì kó wọn wá síwájú Olúwa rẹ ní ọ̀wọ̀ọ̀wọ́. Dájúdájú ẹ ti wá bá Wa (báyìí) gẹ́gẹ́ bí A ṣe da yín nígbà àkọ́kọ́. Àmọ́ ẹ sọ láì ní ẹ̀rí lọ́wọ́ pé A ò níí mú ọjọ́ àdéhùn ṣẹ fún yín.
Verse 49
وَوُضِعَ ٱلْكِتَـٰبُ فَتَرَى ٱلْمُجْرِمِينَ مُشْفِقِينَ مِمَّا فِيهِ وَيَقُولُونَ يَـٰوَيْلَتَنَا مَالِ هَـٰذَا ٱلْكِتَـٰبِ لَا يُغَادِرُ صَغِيرَةً وَلَا كَبِيرَةً إِلَّآ أَحْصَىٰهَا ۚ وَوَجَدُوا۟ مَا عَمِلُوا۟ حَاضِرًا ۗ وَلَا يَظْلِمُ رَبُّكَ أَحَدًا
Transliteration wawuḍiʿa l-kitābu fatarā l-muj'rimīna mush'fiqīna mimmā fīhi wayaqūlūna yāwaylatanā māli hādhā l-kitābi lā yughādiru ṣaghīratan walā kabīratan illā aḥṣāhā wawajadū mā ʿamilū ḥāḍiran walā yaẓlimu rabbuka aḥadan
Yoruba A máa gbé ìwé iṣẹ́ ẹ̀dá kalẹ̀ (fún wọn). Nígbà náà, o máa rí àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ tí wọn yóò máa bẹ̀rù nípa ohun tí ń bẹ nínú ìwé iṣẹ́ wọn. Wọn yóò wí pé: “Ègbé wa! Kí ló mú ìwé yìí ná; kò fi ohun kékeré àti ńlá kan sílẹ̀ láì kọ ọ́ sílẹ̀?” Wọ́n sì bá ohun tí wọ́n ṣe níṣẹ́ níbẹ̀. Olúwa rẹ kò sì níí ṣàbòsí sí ẹnì kan.
Verse 50
وَإِذْ قُلْنَا لِلْمَلَـٰٓئِكَةِ ٱسْجُدُوا۟ لِـَٔادَمَ فَسَجَدُوٓا۟ إِلَّآ إِبْلِيسَ كَانَ مِنَ ٱلْجِنِّ فَفَسَقَ عَنْ أَمْرِ رَبِّهِۦٓ ۗ أَفَتَتَّخِذُونَهُۥ وَذُرِّيَّتَهُۥٓ أَوْلِيَآءَ مِن دُونِى وَهُمْ لَكُمْ عَدُوٌّۢ ۚ بِئْسَ لِلظَّـٰلِمِينَ بَدَلًا
Transliteration wa-idh qul'nā lil'malāikati us'judū liādama fasajadū illā ib'līsa kāna mina l-jini fafasaqa ʿan amri rabbihi afatattakhidhūnahu wadhurriyyatahu awliyāa min dūnī wahum lakum ʿaduwwun bi'sa lilẓẓālimīna badalan
Yoruba (Rántí) nígbà tí A sọ fún àwọn mọlāika pé: “Ẹ forí kanlẹ̀ kí (Ànábì) Ādam.” Wọ́n sì forí kanlẹ̀ kí i àfi ’Iblīs, (tí) ó jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn àlùjànnú. Ó sì yapa sí àṣẹ Olúwa rẹ̀. Nítorí náà, ṣé ẹ máa mú òun àti àwọn àrọ́mọdọ́mọ rẹ̀ ní aláfẹ̀yìntì lẹ́yìn Mi ni, ọ̀tá yín sì ni wọ́n. Pàṣípààrọ̀ tó burú ni fún àwọn alábòsí.1
Verse 51
۞ مَّآ أَشْهَدتُّهُمْ خَلْقَ ٱلسَّمَـٰوَٰتِ وَٱلْأَرْضِ وَلَا خَلْقَ أَنفُسِهِمْ وَمَا كُنتُ مُتَّخِذَ ٱلْمُضِلِّينَ عَضُدًا
Transliteration mā ashhadttuhum khalqa l-samāwāti wal-arḍi walā khalqa anfusihim wamā kuntu muttakhidha l-muḍilīna ʿaḍudan
Yoruba Èmi kò fi wọ́n ṣe ẹlẹ́rìí sí ìṣẹ̀dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀, àti ìṣẹ̀dá àwọn gan-an alára. Èmi kò sì mú àwọn aṣinilọ́nà ní olùrànlọ́wọ́.1
Verse 52
وَيَوْمَ يَقُولُ نَادُوا۟ شُرَكَآءِىَ ٱلَّذِينَ زَعَمْتُمْ فَدَعَوْهُمْ فَلَمْ يَسْتَجِيبُوا۟ لَهُمْ وَجَعَلْنَا بَيْنَهُم مَّوْبِقًا
Transliteration wayawma yaqūlu nādū shurakāiya alladhīna zaʿamtum fadaʿawhum falam yastajībū lahum wajaʿalnā baynahum mawbiqan
Yoruba (Rántí) ọjọ́ tí (Allāhu) yóò sọ pé: “Ẹ pe àwọn akẹgbẹ́ Mi tí ẹ sọ nípa wọn láì ní ẹ̀rí lọ́wọ́ (pé olùṣìpẹ̀ ni wọ́n).” Wọ́n pè wọ́n. Wọn kò sì dá wọn lóhùn. A sì ti fi àyè ìparun sáààrin wọn.
Verse 53
وَرَءَا ٱلْمُجْرِمُونَ ٱلنَّارَ فَظَنُّوٓا۟ أَنَّهُم مُّوَاقِعُوهَا وَلَمْ يَجِدُوا۟ عَنْهَا مَصْرِفًا
Transliteration waraā l-muj'rimūna l-nāra faẓannū annahum muwāqiʿūhā walam yajidū ʿanhā maṣrifan
Yoruba Àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ sì rí Iná. Wọ́n sì mọ̀ dájúdájú pé àwọn yóò kó sínú rẹ̀. Wọn kò sì rí ibùsásí kan kúrò nínú rẹ̀.
Verse 54
وَلَقَدْ صَرَّفْنَا فِى هَـٰذَا ٱلْقُرْءَانِ لِلنَّاسِ مِن كُلِّ مَثَلٍ ۚ وَكَانَ ٱلْإِنسَـٰنُ أَكْثَرَ شَىْءٍ جَدَلًا
Transliteration walaqad ṣarrafnā fī hādhā l-qur'āni lilnnāsi min kulli mathalin wakāna l-insānu akthara shayin jadalan
Yoruba Dájúdájú A ti ṣe àlàyé oníran-ànran sínú al-Ƙur’ān fún àwọn ènìyàn pẹ̀lú gbogbo àkàwé. Ènìyàn sì jẹ́ olùjiyàn ju ohunkóhun lọ.
Verse 55
وَمَا مَنَعَ ٱلنَّاسَ أَن يُؤْمِنُوٓا۟ إِذْ جَآءَهُمُ ٱلْهُدَىٰ وَيَسْتَغْفِرُوا۟ رَبَّهُمْ إِلَّآ أَن تَأْتِيَهُمْ سُنَّةُ ٱلْأَوَّلِينَ أَوْ يَأْتِيَهُمُ ٱلْعَذَابُ قُبُلًا
Transliteration wamā manaʿa l-nāsa an yu'minū idh jāahumu l-hudā wayastaghfirū rabbahum illā an tatiyahum sunnatu l-awalīna aw yatiyahumu l-ʿadhābu qubulan
Yoruba Kò sí ohun tó dí àwọn ènìyàn lọ́wọ́ láti gbàgbọ́ ní òdodo nígbà tí ìmọ̀nà dé bá wọn, (kò sì sí ohun tó dí wọn lọ́wọ́ láti) tọrọ àforíjìn Olúwa wọn, bí kò ṣe pé (wọ́n fẹ́) kí ìṣe (Allāhu nípa ìparun) àwọn ẹni àkọ́kọ́ dé bá àwọn náà tàbí kí ìyà dé bá wọn ní ojúkojú.
Verse 56
وَمَا نُرْسِلُ ٱلْمُرْسَلِينَ إِلَّا مُبَشِّرِينَ وَمُنذِرِينَ ۚ وَيُجَـٰدِلُ ٱلَّذِينَ كَفَرُوا۟ بِٱلْبَـٰطِلِ لِيُدْحِضُوا۟ بِهِ ٱلْحَقَّ ۖ وَٱتَّخَذُوٓا۟ ءَايَـٰتِى وَمَآ أُنذِرُوا۟ هُزُوًا
Transliteration wamā nur'silu l-mur'salīna illā mubashirīna wamundhirīna wayujādilu alladhīna kafarū bil-bāṭili liyud'ḥiḍū bihi l-ḥaqa wa-ittakhadhū āyātī wamā undhirū huzuwan
Yoruba Àti pé A kò rán àwọn Òjíṣẹ́ níṣẹ́ (lásán) àfi kí wọ́n jẹ́ oníròó-ìdùnnú àti olùkìlọ̀. Àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ sì ń fi irọ́ ṣàtakò nítorí kí wọ́n lè fi ba òdodo jẹ́. Wọ́n sì sọ àwọn āyah Mi àti ohun tí A fi ṣèkìlọ̀ fún wọn di yẹ̀yẹ́.
Verse 57
وَمَنْ أَظْلَمُ مِمَّن ذُكِّرَ بِـَٔايَـٰتِ رَبِّهِۦ فَأَعْرَضَ عَنْهَا وَنَسِىَ مَا قَدَّمَتْ يَدَاهُ ۚ إِنَّا جَعَلْنَا عَلَىٰ قُلُوبِهِمْ أَكِنَّةً أَن يَفْقَهُوهُ وَفِىٓ ءَاذَانِهِمْ وَقْرًا ۖ وَإِن تَدْعُهُمْ إِلَى ٱلْهُدَىٰ فَلَن يَهْتَدُوٓا۟ إِذًا أَبَدًا
Transliteration waman aẓlamu mimman dhukkira biāyāti rabbihi fa-aʿraḍa ʿanhā wanasiya mā qaddamat yadāhu innā jaʿalnā ʿalā qulūbihim akinnatan an yafqahūhu wafī ādhānihim waqran wa-in tadʿuhum ilā l-hudā falan yahtadū idhan abadan
Yoruba Ta sì ló ṣàbòsí ju ẹni tí wọ́n fi àwọn āyah Olúwa rẹ̀ ṣèrántí fún, tí ó gbúnrí kúrò níbẹ̀, tí ó sì gbàgbé ohun tí ọwọ́ rẹ̀ méjèèjì tì síwájú? Dájúdájú Àwa fi èbìbò bo ọkàn wọn nítorí kí wọ́n má baà gbọ́ ọ yé. A sì fi èdídí sínú etí wọn. Tí ìwọ bá pè wọ́n síbi ìmọ̀nà, nígbà náà wọn kò sì níí mọ̀nà láéláé.
Verse 58
وَرَبُّكَ ٱلْغَفُورُ ذُو ٱلرَّحْمَةِ ۖ لَوْ يُؤَاخِذُهُم بِمَا كَسَبُوا۟ لَعَجَّلَ لَهُمُ ٱلْعَذَابَ ۚ بَل لَّهُم مَّوْعِدٌ لَّن يَجِدُوا۟ مِن دُونِهِۦ مَوْئِلًا
Transliteration warabbuka l-ghafūru dhū l-raḥmati law yuākhidhuhum bimā kasabū laʿajjala lahumu l-ʿadhāba bal lahum mawʿidun lan yajidū min dūnihi mawilan
Yoruba Olúwa rẹ ni Aláforíjìn, Oníkẹ̀ẹ́. Bí ó bá jẹ́ pé Ó máa fi ohun tí wọ́n ṣe níṣẹ́ mú wọn ni, ìbá tètè mú ìyà wá fún wọn. Ṣùgbọ́n àkókò àdéhùn (àjíǹde) wà fún wọn. Wọn kò sì níí rí ibùsásí kan lẹ́yìn rẹ̀.
Verse 59
وَتِلْكَ ٱلْقُرَىٰٓ أَهْلَكْنَـٰهُمْ لَمَّا ظَلَمُوا۟ وَجَعَلْنَا لِمَهْلِكِهِم مَّوْعِدًا
Transliteration watil'ka l-qurā ahlaknāhum lammā ẓalamū wajaʿalnā limahlikihim mawʿidan
Yoruba Ìwọ́nyí ni àwọn ìlú tí A ti parẹ́ nígbà tí wọ́n ṣàbòsí. A sì fún wọn ní (àkókò) àdéhùn fún ìparun wọn.
Verse 60
وَإِذْ قَالَ مُوسَىٰ لِفَتَىٰهُ لَآ أَبْرَحُ حَتَّىٰٓ أَبْلُغَ مَجْمَعَ ٱلْبَحْرَيْنِ أَوْ أَمْضِىَ حُقُبًا
Transliteration wa-idh qāla mūsā lifatāhu lā abraḥu ḥattā ablugha majmaʿa l-baḥrayni aw amḍiya ḥuquban
Yoruba (Rántí) nígbà tí (Ànábì) Mūsā sọ fún ọmọ-ọ̀dọ̀ rẹ̀ pé: “Èmi kò níí yé rìn títí mo máa fi dé ibi tí odò méjì ti papọ̀ tàbí (títí) mo máa fi lo ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ọdún.”
Verse 61
فَلَمَّا بَلَغَا مَجْمَعَ بَيْنِهِمَا نَسِيَا حُوتَهُمَا فَٱتَّخَذَ سَبِيلَهُۥ فِى ٱلْبَحْرِ سَرَبًا
Transliteration falammā balaghā majmaʿa baynihimā nasiyā ḥūtahumā fa-ittakhadha sabīlahu fī l-baḥri saraban
Yoruba Nígbà tí àwọn méjèèjì sì dé ibi tí odò méjèèjì ti papọ̀, wọ́n gbàgbé ẹja wọn. (Ẹja náà) sì sọ ojú ọ̀nà rẹ̀ di poro ọ̀nà nínú odò.
Verse 62
فَلَمَّا جَاوَزَا قَالَ لِفَتَىٰهُ ءَاتِنَا غَدَآءَنَا لَقَدْ لَقِينَا مِن سَفَرِنَا هَـٰذَا نَصَبًا
Transliteration falammā jāwazā qāla lifatāhu ātinā ghadāanā laqad laqīnā min safarinā hādhā naṣaban
Yoruba Nígbà tí àwọn méjèèjì ré kọjá (àyè náà), ó sọ fún ọmọ-ọ̀dọ̀ rẹ̀ pé: “Fún wa ní oúnjẹ ọ̀sán wa. Dájúdájú a ti ko wàhálà nínú ìrìn-àjò wa yìí.”
Verse 63
قَالَ أَرَءَيْتَ إِذْ أَوَيْنَآ إِلَى ٱلصَّخْرَةِ فَإِنِّى نَسِيتُ ٱلْحُوتَ وَمَآ أَنسَىٰنِيهُ إِلَّا ٱلشَّيْطَـٰنُ أَنْ أَذْكُرَهُۥ ۚ وَٱتَّخَذَ سَبِيلَهُۥ فِى ٱلْبَحْرِ عَجَبًا
Transliteration qāla ara-ayta idh awaynā ilā l-ṣakhrati fa-innī nasītu l-ḥūta wamā ansānīhu illā l-shayṭānu an adhkurahu wa-ittakhadha sabīlahu fī l-baḥri ʿajaban
Yoruba (Ọmọ-ọ̀dọ̀ rẹ̀) sọ pé: “Ṣé o rí i! Nígbà tí a wà níbi àpáta (fún ìsinmi), dájúdájú mo ti gbàgbé ẹja náà (síbẹ̀)? Kò sì sí ohun tí ó mú mi gbàgbé rẹ̀ bí kò ṣe Èṣù, tí kò jẹ́ kí n̄g rántí rẹ̀. (Ẹja náà) sì ti mú ọ̀nà rẹ̀ tọ̀ lọ nínú odò ní ọ̀nà ìyanu.”
Verse 64
قَالَ ذَٰلِكَ مَا كُنَّا نَبْغِ ۚ فَٱرْتَدَّا عَلَىٰٓ ءَاثَارِهِمَا قَصَصًا
Transliteration qāla dhālika mā kunnā nabghi fa-ir'taddā ʿalā āthārihimā qaṣaṣan
Yoruba (Ànábì Mūsā) sọ pé: “(Ibi tí ẹja ti lọ) yẹn ni ohun tí à ń wá.”Àwọn méjèèjì sì padà sẹ́yìn láti tọ orípa ẹsẹ̀ wọn bí wọ́n ti ṣe tọ̀ ọ́ wá.
Verse 65
فَوَجَدَا عَبْدًا مِّنْ عِبَادِنَآ ءَاتَيْنَـٰهُ رَحْمَةً مِّنْ عِندِنَا وَعَلَّمْنَـٰهُ مِن لَّدُنَّا عِلْمًا
Transliteration fawajadā ʿabdan min ʿibādinā ātaynāhu raḥmatan min ʿindinā waʿallamnāhu min ladunnā ʿil'man
Yoruba Àwọn méjèèjì sì bá ẹrúsìn kan nínú àwọn ẹrúsìn Wa (níbẹ̀), tí A fún ní ìkẹ́ kan láti ọ̀dọ̀ Wa. A sì fún un ní ìmọ̀ láti ọ̀dọ̀ Wa.
Verse 66
قَالَ لَهُۥ مُوسَىٰ هَلْ أَتَّبِعُكَ عَلَىٰٓ أَن تُعَلِّمَنِ مِمَّا عُلِّمْتَ رُشْدًا
Transliteration qāla lahu mūsā hal attabiʿuka ʿalā an tuʿallimani mimmā ʿullim'ta rush'dan
Yoruba (Ànábì) Mūsā sọ fún un pé: “Ṣé kí n̄g tẹ̀lé ọ nítorí kí o lè kọ́ mi nínú ohun tí Wọ́n fi mọ̀ ọ́ ní ìmọ̀nà.”1
Verse 67
قَالَ إِنَّكَ لَن تَسْتَطِيعَ مَعِىَ صَبْرًا
Transliteration qāla innaka lan tastaṭīʿa maʿiya ṣabran
Yoruba (Kidr) sọ pé: “Dájúdájú ìwọ kò lè ṣe sùúrù pẹ̀lú mi.
Verse 68
وَكَيْفَ تَصْبِرُ عَلَىٰ مَا لَمْ تُحِطْ بِهِۦ خُبْرًا
Transliteration wakayfa taṣbiru ʿalā mā lam tuḥiṭ bihi khub'ran
Yoruba Àti pé báwo ni o ṣe máa ṣe sùúrù lórí ohun tí o ò fi ìmọ̀ rọkiri ká rẹ̀?”
Verse 69
قَالَ سَتَجِدُنِىٓ إِن شَآءَ ٱللَّهُ صَابِرًا وَلَآ أَعْصِى لَكَ أَمْرًا
Transliteration qāla satajidunī in shāa l-lahu ṣābiran walā aʿṣī laka amran
Yoruba (Ànábì Mūsā) sọ pé: “Tí Allāhu bá fẹ́, ó máa bá mi ní onísùúrù. Èmi kò sì níí yapa àṣẹ rẹ.”
Verse 70
قَالَ فَإِنِ ٱتَّبَعْتَنِى فَلَا تَسْـَٔلْنِى عَن شَىْءٍ حَتَّىٰٓ أُحْدِثَ لَكَ مِنْهُ ذِكْرًا
Transliteration qāla fa-ini ittabaʿtanī falā tasalnī ʿan shayin ḥattā uḥ'ditha laka min'hu dhik'ran
Yoruba (Kidr) sọ pé: “Tí o bá tẹ̀lé mi, má ṣe bi mí ní ìbéèrè nípa n̄ǹkan kan títí mo fi máa kọ́kọ́ mú ìrántí wá fún ọ nípa rẹ̀.”
Verse 71
فَٱنطَلَقَا حَتَّىٰٓ إِذَا رَكِبَا فِى ٱلسَّفِينَةِ خَرَقَهَا ۖ قَالَ أَخَرَقْتَهَا لِتُغْرِقَ أَهْلَهَا لَقَدْ جِئْتَ شَيْـًٔا إِمْرًا
Transliteration fa-inṭalaqā ḥattā idhā rakibā fī l-safīnati kharaqahā qāla akharaqtahā litugh'riqa ahlahā laqad ji'ta shayan im'ran
Yoruba Nítorí náà, àwọn méjèèjì lọ títí di ìgbà tí wọ́n fi wọ inú ọkọ̀ ojú-omi. (Kidr) sì dá ọkọ̀ náà lu. (Ànábì Mūsā) sọ pé: “O ṣe dá a lu, (ṣé) kí àwọn èrò rẹ̀ lè tẹ̀ rì ni? Dájúdájú o ti ṣe n̄ǹkan aburú kan!”
Verse 72
قَالَ أَلَمْ أَقُلْ إِنَّكَ لَن تَسْتَطِيعَ مَعِىَ صَبْرًا
Transliteration qāla alam aqul innaka lan tastaṭīʿa maʿiya ṣabran
Yoruba (Kidr) sọ pé: “Ǹjẹ́ èmi kò sọ fún ọ pé dájúdájú ìwọ kò níí lè ṣe sùúrú pẹ̀lú mi.”
Verse 73
قَالَ لَا تُؤَاخِذْنِى بِمَا نَسِيتُ وَلَا تُرْهِقْنِى مِنْ أَمْرِى عُسْرًا
Transliteration qāla lā tuākhidh'nī bimā nasītu walā tur'hiq'nī min amrī ʿus'ran
Yoruba (Ànábì Mūsā) sọ pé: “Má ṣe bá mi wí nípa ohun tí mo gbàgbé. Má sì ṣe kó ìnira bá mi nínú ọ̀rọ̀ (ìrìn-àjò) mi (pẹ̀lú rẹ).”
Verse 74
فَٱنطَلَقَا حَتَّىٰٓ إِذَا لَقِيَا غُلَـٰمًا فَقَتَلَهُۥ قَالَ أَقَتَلْتَ نَفْسًا زَكِيَّةًۢ بِغَيْرِ نَفْسٍ لَّقَدْ جِئْتَ شَيْـًٔا نُّكْرًا
Transliteration fa-inṭalaqā ḥattā idhā laqiyā ghulāman faqatalahu qāla aqatalta nafsan zakiyyatan bighayri nafsin laqad ji'ta shayan nuk'ran
Yoruba Lẹ́yìn náà, àwọn méjèèjì lọ títí di ìgbà tí wọ́n fi pàdé ọmọdékùnrin kan. (Kidr) sì pa á. (Ànábì Mūsā) sọ pé: “O ṣe pa ẹ̀mí (ènìyàn) mímọ́, láì gba ẹ̀mí? Dájúdájú o ti ṣe n̄ǹkan aburú o.”
Verse 75
۞ قَالَ أَلَمْ أَقُل لَّكَ إِنَّكَ لَن تَسْتَطِيعَ مَعِىَ صَبْرًا
Transliteration qāla alam aqul laka innaka lan tastaṭīʿa maʿiya ṣabran
Yoruba (Kidr) sọ pé: “Ǹjẹ́ èmi kò sọ fún ọ pé dájúdájú ìwọ kò níí lè ṣe sùúrú pẹ̀lú mi.”
Verse 76
قَالَ إِن سَأَلْتُكَ عَن شَىْءٍۭ بَعْدَهَا فَلَا تُصَـٰحِبْنِى ۖ قَدْ بَلَغْتَ مِن لَّدُنِّى عُذْرًا
Transliteration qāla in sa-altuka ʿan shayin baʿdahā falā tuṣāḥib'nī qad balaghta min ladunnī ʿudh'ran
Yoruba (Ànábì Mūsā) sọ pé: “Tí mo bá tún bi ọ́ nípa kiní kan lẹ́yìn rẹ̀, má ṣe bá mi rìn mọ́. Dájúdájú o ti mú àwáwí dé òpin lọ́dọ̀ mi.”
Verse 77
فَٱنطَلَقَا حَتَّىٰٓ إِذَآ أَتَيَآ أَهْلَ قَرْيَةٍ ٱسْتَطْعَمَآ أَهْلَهَا فَأَبَوْا۟ أَن يُضَيِّفُوهُمَا فَوَجَدَا فِيهَا جِدَارًا يُرِيدُ أَن يَنقَضَّ فَأَقَامَهُۥ ۖ قَالَ لَوْ شِئْتَ لَتَّخَذْتَ عَلَيْهِ أَجْرًا
Transliteration fa-inṭalaqā ḥattā idhā atayā ahla qaryatin is'taṭʿamā ahlahā fa-abaw an yuḍayyifūhumā fawajadā fīhā jidāran yurīdu an yanqaḍḍa fa-aqāmahu qāla law shi'ta lattakhadhta ʿalayhi ajran
Yoruba Lẹ́yìn náà, àwọn méjèèjì lọ títí di ìgbà tí wọ́n dé ọ̀dọ̀ àwọn ará ìlú kan. Wọ́n tọrọ oúnjẹ lọ́dọ̀ àwọn ará ìlú náà. Wọ́n sì kọ̀ láti ṣe wọ́n ní àlejò. Àwọn méjèèjì sì bá ògiri kan níbẹ̀ tí ó fẹ́ wó. (Kidr) sì gbé e dìde. (Ànábì Mūsā) sọ pé: “Tí ó bá jẹ́ pé o bá fẹ́, kí o sì gba owó-ọ̀yà lórí rẹ̀.”
Verse 78
قَالَ هَـٰذَا فِرَاقُ بَيْنِى وَبَيْنِكَ ۚ سَأُنَبِّئُكَ بِتَأْوِيلِ مَا لَمْ تَسْتَطِع عَّلَيْهِ صَبْرًا
Transliteration qāla hādhā firāqu baynī wabaynika sa-unabbi-uka bitawīli mā lam tastaṭiʿ ʿalayhi ṣabran
Yoruba (Kidr) sọ pé: “Èyí ni òpínyà láààrin èmi àti ìwọ. Mo sì máa fún ọ ní ìtúmọ̀ ohun tí ìwọ kò lè ṣe sùúrù lórí rẹ̀.”
Verse 79
أَمَّا ٱلسَّفِينَةُ فَكَانَتْ لِمَسَـٰكِينَ يَعْمَلُونَ فِى ٱلْبَحْرِ فَأَرَدتُّ أَنْ أَعِيبَهَا وَكَانَ وَرَآءَهُم مَّلِكٌ يَأْخُذُ كُلَّ سَفِينَةٍ غَصْبًا
Transliteration ammā l-safīnatu fakānat limasākīna yaʿmalūna fī l-baḥri fa-aradttu an aʿībahā wakāna warāahum malikun yakhudhu kulla safīnatin ghaṣban
Yoruba Ní ti ọkọ̀ ojú-omi, ó jẹ́ ti àwọn mẹ̀kúnnù tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ lórí omi. Mo sì fẹ́ láti fi àlébù kàn án (nítorí pé), ọba kan wà níwájú wọn tó ń gba gbogbo ọkọ̀ ojú-omi pẹ̀lú ipá.
Verse 80
وَأَمَّا ٱلْغُلَـٰمُ فَكَانَ أَبَوَاهُ مُؤْمِنَيْنِ فَخَشِينَآ أَن يُرْهِقَهُمَا طُغْيَـٰنًا وَكُفْرًا
Transliteration wa-ammā l-ghulāmu fakāna abawāhu mu'minayni fakhashīnā an yur'hiqahumā ṭugh'yānan wakuf'ran
Yoruba Ní ti ọmọdékùnrin náà, àwọn òbí rẹ̀ méjèèjì jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo. A sì ń bẹ̀rù pé kí ó màa kó ìtayọ ẹnu-ààlà àti àìgbàgbọ́ bá àwọn méjèèjì.1
Verse 81
فَأَرَدْنَآ أَن يُبْدِلَهُمَا رَبُّهُمَا خَيْرًا مِّنْهُ زَكَوٰةً وَأَقْرَبَ رُحْمًا
Transliteration fa-aradnā an yub'dilahumā rabbuhumā khayran min'hu zakatan wa-aqraba ruḥ'man
Yoruba Nítorí náà, A fẹ́ kí Olúwa àwọn méjèèjì pààrọ̀ rẹ̀ fún wọn pẹ̀lú (èyí) tó lóore jù ú lọ tó máa jẹ́ ẹni mímọ́ jù ú lọ àti (èyí) tó máa jẹ́ ọmọ rere olújú-àánú sí (àwọn òbí rẹ̀) jù ú lọ.
Verse 82
وَأَمَّا ٱلْجِدَارُ فَكَانَ لِغُلَـٰمَيْنِ يَتِيمَيْنِ فِى ٱلْمَدِينَةِ وَكَانَ تَحْتَهُۥ كَنزٌ لَّهُمَا وَكَانَ أَبُوهُمَا صَـٰلِحًا فَأَرَادَ رَبُّكَ أَن يَبْلُغَآ أَشُدَّهُمَا وَيَسْتَخْرِجَا كَنزَهُمَا رَحْمَةً مِّن رَّبِّكَ ۚ وَمَا فَعَلْتُهُۥ عَنْ أَمْرِى ۚ ذَٰلِكَ تَأْوِيلُ مَا لَمْ تَسْطِع عَّلَيْهِ صَبْرًا
Transliteration wa-ammā l-jidāru fakāna lighulāmayni yatīmayni fī l-madīnati wakāna taḥtahu kanzun lahumā wakāna abūhumā ṣāliḥan fa-arāda rabbuka an yablughā ashuddahumā wayastakhrijā kanzahumā raḥmatan min rabbika wamā faʿaltuhu ʿan amrī dhālika tawīlu mā lam tasṭiʿ ʿalayhi ṣabran
Yoruba Nípa ti ògiri, ó jẹ́ ti àwọn ọmọdékùnrin, ọmọ òrukàn méjì kan nínú ìlú náà. Àpótí-ọrọ̀ kan sì ń bẹ fún àwọn méjèèjì lábẹ́ ògiri náà. Bàbá àwọn méjèèjì sì jẹ́ ẹni rere. Nítorí náà, Olúwa rẹ fẹ́ kí àwọn méjèèjì dàgbà dáadáa (bá dúkìá náà), kí wọ́n sì hú dúkìá wọn jáde (kí ó lè jẹ́) ìkẹ́ kan láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ. Èmi kò dá a ṣe láti ọ̀dọ̀ ara mi; (Allāhu l’Ó pa mí láṣẹ rẹ̀). Ìyẹn ni ìtúmọ̀ ohun tí ìwọ kò lè ṣe sùúrù fún.
Verse 83
وَيَسْـَٔلُونَكَ عَن ذِى ٱلْقَرْنَيْنِ ۖ قُلْ سَأَتْلُوا۟ عَلَيْكُم مِّنْهُ ذِكْرًا
Transliteration wayasalūnaka ʿan dhī l-qarnayni qul sa-atlū ʿalaykum min'hu dhik'ran
Yoruba Wọ́n ń bi ọ́ léèrè nípa Thul-Ƙọrneen. Sọ pé: “Mo máa mú ọ̀rọ̀ ìrántí wá fún yín nípa rẹ̀.”
Verse 84
إِنَّا مَكَّنَّا لَهُۥ فِى ٱلْأَرْضِ وَءَاتَيْنَـٰهُ مِن كُلِّ شَىْءٍ سَبَبًا
Transliteration innā makkannā lahu fī l-arḍi waātaynāhu min kulli shayin sababan
Yoruba Dájúdájú Àwa fún un ní ipò lórí ilẹ̀. A sì fún un ní ọ̀nà tó lè gbà ṣe gbogbo n̄ǹkan (tí ó bá fẹ́ ṣe).
Verse 85
فَأَتْبَعَ سَبَبًا
Transliteration fa-atbaʿa sababan
Yoruba Nítorí náà, ó mú ọ̀nà kan tọ̀
Verse 86
حَتَّىٰٓ إِذَا بَلَغَ مَغْرِبَ ٱلشَّمْسِ وَجَدَهَا تَغْرُبُ فِى عَيْنٍ حَمِئَةٍ وَوَجَدَ عِندَهَا قَوْمًا ۗ قُلْنَا يَـٰذَا ٱلْقَرْنَيْنِ إِمَّآ أَن تُعَذِّبَ وَإِمَّآ أَن تَتَّخِذَ فِيهِمْ حُسْنًا
Transliteration ḥattā idhā balagha maghriba l-shamsi wajadahā taghrubu fī ʿaynin ḥami-atin wawajada ʿindahā qawman qul'nā yādhā l-qarnayni immā an tuʿadhiba wa-immā an tattakhidha fīhim ḥus'nan
Yoruba títí ó fi dé ibùwọ̀ òòrùn ayé. Ó rí i tí ń wọ̀ sínú ìṣẹ́lẹ̀rú pẹ̀tẹ̀pẹ́tẹ̀ dúdú kan. Ó sì bá àwọn ènìyàn kan níbẹ̀. A sọ pé: “Thul-Ƙọrneen, yálà kí o jẹ wọ́n níyà tàbí kí o mú ohun rere jáde lára wọn.”
Verse 87
قَالَ أَمَّا مَن ظَلَمَ فَسَوْفَ نُعَذِّبُهُۥ ثُمَّ يُرَدُّ إِلَىٰ رَبِّهِۦ فَيُعَذِّبُهُۥ عَذَابًا نُّكْرًا
Transliteration qāla ammā man ẓalama fasawfa nuʿadhibuhu thumma yuraddu ilā rabbihi fayuʿadhibuhu ʿadhāban nuk'ran
Yoruba (Allāhu) sọ pé: “Ní ti ẹni tí ó bá ṣàbòsí, láìpẹ́ A máa jẹ ẹ́ níyà. Lẹ́yìn náà, wọn máa dá a padà sí ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ̀. Ó sì máa jẹ ẹ́ níyà tó burú.
Verse 88
وَأَمَّا مَنْ ءَامَنَ وَعَمِلَ صَـٰلِحًا فَلَهُۥ جَزَآءً ٱلْحُسْنَىٰ ۖ وَسَنَقُولُ لَهُۥ مِنْ أَمْرِنَا يُسْرًا
Transliteration wa-ammā man āmana waʿamila ṣāliḥan falahu jazāan l-ḥus'nā wasanaqūlu lahu min amrinā yus'ran
Yoruba Ṣùgbọ́n ní ti ẹni tí ó bá gbàgbọ́ ní òdodo, tí ó sì ṣe iṣẹ́ rere, tirẹ̀ ni ẹ̀san rere. A ó sì sọ̀rọ̀ ìrọ̀rùn fún un nínú àṣẹ Wa.”
Verse 89
ثُمَّ أَتْبَعَ سَبَبًا
Transliteration thumma atbaʿa sababan
Yoruba Lẹ́yìn náà, ó mú ọ̀nà kan tọ̀
Verse 90
حَتَّىٰٓ إِذَا بَلَغَ مَطْلِعَ ٱلشَّمْسِ وَجَدَهَا تَطْلُعُ عَلَىٰ قَوْمٍ لَّمْ نَجْعَل لَّهُم مِّن دُونِهَا سِتْرًا
Transliteration ḥattā idhā balagha maṭliʿa l-shamsi wajadahā taṭluʿu ʿalā qawmin lam najʿal lahum min dūnihā sit'ran
Yoruba títí ó fi dé ibùyọ òòrùn ayé. Ó rí i tí ń yọ lórí àwọn ènìyàn kan, tí A kò fún ní gàgá (ààbò) kan níbi òòrùn.
Verse 91
كَذَٰلِكَ وَقَدْ أَحَطْنَا بِمَا لَدَيْهِ خُبْرًا
Transliteration kadhālika waqad aḥaṭnā bimā ladayhi khub'ran
Yoruba Báyẹn ni (Thul-Ƙọrneen ṣe ń tẹ̀ síwájú). Dájúdájú A rọkiriká ohun tí ń bẹ lọ́dọ̀ rẹ̀ pẹ̀lú ìmọ̀.
Verse 92
ثُمَّ أَتْبَعَ سَبَبًا
Transliteration thumma atbaʿa sababan
Yoruba Lẹ́yìn náà, ó mú ọ̀nà kan tọ̀
Verse 93
حَتَّىٰٓ إِذَا بَلَغَ بَيْنَ ٱلسَّدَّيْنِ وَجَدَ مِن دُونِهِمَا قَوْمًا لَّا يَكَادُونَ يَفْقَهُونَ قَوْلًا
Transliteration ḥattā idhā balagha bayna l-sadayni wajada min dūnihimā qawman lā yakādūna yafqahūna qawlan
Yoruba títí ó fi dé ààrin àpáta méjì. Ó sì bá àwọn ènìyàn kan níwájú rẹ̀. Wọn kò sì fẹ́ẹ̀ gbọ́ àgbọ́yé ọ̀rọ̀ kan (nínú èdè mìíràn).
Verse 94
قَالُوا۟ يَـٰذَا ٱلْقَرْنَيْنِ إِنَّ يَأْجُوجَ وَمَأْجُوجَ مُفْسِدُونَ فِى ٱلْأَرْضِ فَهَلْ نَجْعَلُ لَكَ خَرْجًا عَلَىٰٓ أَن تَجْعَلَ بَيْنَنَا وَبَيْنَهُمْ سَدًّا
Transliteration qālū yādhā l-qarnayni inna yajūja wamajūja muf'sidūna fī l-arḍi fahal najʿalu laka kharjan ʿalā an tajʿala baynanā wabaynahum saddan
Yoruba Wọ́n sọ pé: “Thul-Ƙọrneen, dájúdájú (ìran) Ya’jūj àti Ma’jūj ń ṣe ìbàjẹ́ lórí ilẹ̀. Ṣé kí á fún ọ ní owó-òde nítorí kí o lè bá wa mọ odi kan sáààrin àwa àti àwọn?”
Verse 95
قَالَ مَا مَكَّنِّى فِيهِ رَبِّى خَيْرٌ فَأَعِينُونِى بِقُوَّةٍ أَجْعَلْ بَيْنَكُمْ وَبَيْنَهُمْ رَدْمًا
Transliteration qāla mā makkannī fīhi rabbī khayrun fa-aʿīnūnī biquwwatin ajʿal baynakum wabaynahum radman
Yoruba Ó sọ pé: “Ohun tí Olúwa mi fún mi nínú ipò lóore jùlọ. Nítorí náà, ẹ fi agbára ràn mí lọ́wọ́ ni nítorí kí n̄g lè mọ odi sáààrin ẹ̀yin àti àwọn.
Verse 96
ءَاتُونِى زُبَرَ ٱلْحَدِيدِ ۖ حَتَّىٰٓ إِذَا سَاوَىٰ بَيْنَ ٱلصَّدَفَيْنِ قَالَ ٱنفُخُوا۟ ۖ حَتَّىٰٓ إِذَا جَعَلَهُۥ نَارًا قَالَ ءَاتُونِىٓ أُفْرِغْ عَلَيْهِ قِطْرًا
Transliteration ātūnī zubara l-ḥadīdi ḥattā idhā sāwā bayna l-ṣadafayni qāla unfukhū ḥattā idhā jaʿalahu nāran qāla ātūnī uf'righ ʿalayhi qiṭ'ran
Yoruba Ẹ máa fún mi ni ègígé irin títí di ìgbà tí ó fi máa bá ẹ̀gbẹ́ àpáta méjèèjì dọ́gba.” Ó sọ pé: “Ẹ máa fẹ́ atẹ́gùn ẹwìrì (sí i lára) títí di ìgbà tí ó máa (pọ́n wẹ̀ẹ̀ bí) iná.” Ó sọ pé: “Ẹ mu idẹ wá fún mi kí n̄g yọ́ ọ lé e lórí.”
Verse 97
فَمَا ٱسْطَـٰعُوٓا۟ أَن يَظْهَرُوهُ وَمَا ٱسْتَطَـٰعُوا۟ لَهُۥ نَقْبًا
Transliteration famā is'ṭāʿū an yaẓharūhu wamā is'taṭāʿū lahu naqban
Yoruba Nítorí náà, wọn kò lè gùn ún, wọn kò sì lè dá a lu.
Verse 98
قَالَ هَـٰذَا رَحْمَةٌ مِّن رَّبِّى ۖ فَإِذَا جَآءَ وَعْدُ رَبِّى جَعَلَهُۥ دَكَّآءَ ۖ وَكَانَ وَعْدُ رَبِّى حَقًّا
Transliteration qāla hādhā raḥmatun min rabbī fa-idhā jāa waʿdu rabbī jaʿalahu dakkāa wakāna waʿdu rabbī ḥaqqan
Yoruba Ó sọ pé: “Èyí ni ìkẹ́ kan láti ọ̀dọ̀ Olúwa mi. Nígbà tí àdéhùn Olúwa mi bá dé, (Allāhu) yó sì sọ ọ́ di pẹ̀tẹ́lẹ̀. Àdéhùn Olúwa mi sì jẹ́ òdodo.”
Verse 99
۞ وَتَرَكْنَا بَعْضَهُمْ يَوْمَئِذٍ يَمُوجُ فِى بَعْضٍ ۖ وَنُفِخَ فِى ٱلصُّورِ فَجَمَعْنَـٰهُمْ جَمْعًا
Transliteration wataraknā baʿḍahum yawma-idhin yamūju fī baʿḍin wanufikha fī l-ṣūri fajamaʿnāhum jamʿan
Yoruba A máa fi àwọn (ènìyàn àti àlùjànnú) sílẹ̀ ní ọjọ́ yẹn, tí apá kan wọn yó sì máa rúpọ̀ mọ́ apá kan. Wọ́n á fọn fèrè oníwo fún àjíǹde. A ó sì kó gbogbo wọn jọ papọ̀ pátápátá.
Verse 100
وَعَرَضْنَا جَهَنَّمَ يَوْمَئِذٍ لِّلْكَـٰفِرِينَ عَرْضًا
Transliteration waʿaraḍnā jahannama yawma-idhin lil'kāfirīna ʿarḍan
Yoruba Ní ọjọ́ yẹn, A ó sì fi iná Jahanamọ han àwọn aláìgbàgbọ́ kedere.
Verse 101
ٱلَّذِينَ كَانَتْ أَعْيُنُهُمْ فِى غِطَآءٍ عَن ذِكْرِى وَكَانُوا۟ لَا يَسْتَطِيعُونَ سَمْعًا
Transliteration alladhīna kānat aʿyunuhum fī ghiṭāin ʿan dhik'rī wakānū lā yastaṭīʿūna samʿan
Yoruba (Àwọn ni) àwọn tí ojú wọn wà nínú èbìbò nípa ìrántí Mi. Wọn kò sì lè gbọ́rọ̀.
Verse 102
أَفَحَسِبَ ٱلَّذِينَ كَفَرُوٓا۟ أَن يَتَّخِذُوا۟ عِبَادِى مِن دُونِىٓ أَوْلِيَآءَ ۚ إِنَّآ أَعْتَدْنَا جَهَنَّمَ لِلْكَـٰفِرِينَ نُزُلًا
Transliteration afaḥasiba alladhīna kafarū an yattakhidhū ʿibādī min dūnī awliyāa innā aʿtadnā jahannama lil'kāfirīna nuzulan
Yoruba Ṣé àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ lérò pé àwọn yóò mú àwọn ẹrúsìn Mi ní alátìlẹ́yìn lẹ́yìn Mi ni? Dájúdájú Àwa pèsè iná Jahanamọ sílẹ̀ ní ibùdésí fún àwọn aláìgbàgbọ́.
Verse 103
قُلْ هَلْ نُنَبِّئُكُم بِٱلْأَخْسَرِينَ أَعْمَـٰلًا
Transliteration qul hal nunabbi-ukum bil-akhsarīna aʿmālan
Yoruba Sọ pé: “Ṣé kí Á fún yín ní ìró àwọn ẹni òfò jùlọ nípa iṣẹ́ (ọwọ́ wọn)?
Verse 104
ٱلَّذِينَ ضَلَّ سَعْيُهُمْ فِى ٱلْحَيَوٰةِ ٱلدُّنْيَا وَهُمْ يَحْسَبُونَ أَنَّهُمْ يُحْسِنُونَ صُنْعًا
Transliteration alladhīna ḍalla saʿyuhum fī l-ḥayati l-dun'yā wahum yaḥsabūna annahum yuḥ'sinūna ṣun'ʿan
Yoruba (Àwọn ni) àwọn tí iṣẹ́ wọn ti bàjẹ́ nínú ìṣẹ̀mí ayé, (àmọ́ tí) wọ́n ń lérò pé dájúdájú àwọn ń ṣe iṣẹ́ rere.
Verse 105
أُو۟لَـٰٓئِكَ ٱلَّذِينَ كَفَرُوا۟ بِـَٔايَـٰتِ رَبِّهِمْ وَلِقَآئِهِۦ فَحَبِطَتْ أَعْمَـٰلُهُمْ فَلَا نُقِيمُ لَهُمْ يَوْمَ ٱلْقِيَـٰمَةِ وَزْنًا
Transliteration ulāika alladhīna kafarū biāyāti rabbihim waliqāihi faḥabiṭat aʿmāluhum falā nuqīmu lahum yawma l-qiyāmati waznan
Yoruba Àwọn wọ̀nyẹn ni àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ nínú àwọn āyah Olúwa wọn àti ìpàdé Rẹ̀. Àwọn iṣẹ́ wọn sì bàjẹ́. Nítorí náà, A ò níí jẹ́ kí wọ́n jámọ́ n̄ǹkan kan lórí ìwọ̀n ní Ọjọ́ Àjíǹde.
Verse 106
ذَٰلِكَ جَزَآؤُهُمْ جَهَنَّمُ بِمَا كَفَرُوا۟ وَٱتَّخَذُوٓا۟ ءَايَـٰتِى وَرُسُلِى هُزُوًا
Transliteration dhālika jazāuhum jahannamu bimā kafarū wa-ittakhadhū āyātī warusulī huzuwan
Yoruba Jahanamọ, ìyẹn ni ẹ̀san wọn nítorí pé wọ́n ṣàì gbàgbọ́, wọ́n sì sọ àwọn āyah Mi àti àwọn Òjíṣẹ́ Mi di oníyẹ̀yẹ́.
Verse 107
إِنَّ ٱلَّذِينَ ءَامَنُوا۟ وَعَمِلُوا۟ ٱلصَّـٰلِحَـٰتِ كَانَتْ لَهُمْ جَنَّـٰتُ ٱلْفِرْدَوْسِ نُزُلًا
Transliteration inna alladhīna āmanū waʿamilū l-ṣāliḥāti kānat lahum jannātu l-fir'dawsi nuzulan
Yoruba Dájúdájú àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe àwọn iṣẹ́ rere, àwọn ọgbà Firdaos ti wà fún wọn ní ibùdésí.
Verse 108
خَـٰلِدِينَ فِيهَا لَا يَبْغُونَ عَنْهَا حِوَلًا
Transliteration khālidīna fīhā lā yabghūna ʿanhā ḥiwalan
Yoruba Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀. Wọn kò sì níí fẹ́ kúrò nínú rẹ̀.
Verse 109
قُل لَّوْ كَانَ ٱلْبَحْرُ مِدَادًا لِّكَلِمَـٰتِ رَبِّى لَنَفِدَ ٱلْبَحْرُ قَبْلَ أَن تَنفَدَ كَلِمَـٰتُ رَبِّى وَلَوْ جِئْنَا بِمِثْلِهِۦ مَدَدًا
Transliteration qul law kāna l-baḥru midādan likalimāti rabbī lanafida l-baḥru qabla an tanfada kalimātu rabbī walaw ji'nā bimith'lihi madadan
Yoruba Sọ pé: “Tí ó bá jẹ́ pé ibúdò jẹ́ tàdáà fún àwọn ọ̀rọ̀ Olúwa Mi, ibúdò kúkú máa tán ṣíwájú kí àwọn ọ̀rọ̀ Olúwa Mi tó tán, kódà kí Á tún mú (ibúdò) irú rẹ̀ wá ní àlékún.”
Verse 110
قُلْ إِنَّمَآ أَنَا۠ بَشَرٌ مِّثْلُكُمْ يُوحَىٰٓ إِلَىَّ أَنَّمَآ إِلَـٰهُكُمْ إِلَـٰهٌ وَٰحِدٌ ۖ فَمَن كَانَ يَرْجُوا۟ لِقَآءَ رَبِّهِۦ فَلْيَعْمَلْ عَمَلًا صَـٰلِحًا وَلَا يُشْرِكْ بِعِبَادَةِ رَبِّهِۦٓ أَحَدًۢا
Transliteration qul innamā anā basharun mith'lukum yūḥā ilayya annamā ilāhukum ilāhun wāḥidun faman kāna yarjū liqāa rabbihi falyaʿmal ʿamalan ṣāliḥan walā yush'rik biʿibādati rabbihi aḥadan
Yoruba Sọ pé: “Abara ni èmi bí irú yín. Wọ́n ń fí ìmísí ránṣẹ́ sí mi pé Ọlọ́hun yín, Ọlọ́hun Ọ̀kan ṣoṣo ni. Nítorí náà, ẹnikẹ́ni tí ó bá ń retí ìpàdé Olúwa rẹ̀, kí ó ṣe iṣẹ́ rere. Kò sì gbọdọ̀ fi ẹnì kan kan ṣe akẹgbẹ́ níbi jíjọ́sìn fún Olúwa rẹ̀ (kò gbọ́dọ̀ ṣẹbọ sí Olúwa rẹ̀).”
Read Surah Al-Kahf in another language
- English (word by word)
- Albanian
- Amazigh
- Amharic
- Assamese
- Azerbaijani
- Bambara
- Bangla
- Bosnian
- Bulgarian
- Chechen
- Chinese
- Czech
- Dari
- Dhivehi
- Dutch
- Finnish
- French
- German
- Gujarati
- Hausa
- Hebrew
- Hindi
- Indonesian
- Italian
- Japanese
- Kannada
- Kazakh
- Khmer
- Kinyarwanda
- Korean
- Kurdish
- Luganda
- Malay
- Malayalam
- Maranao
- Marathi
- Nepali
- Norwegian
- Oromo
- Pashto
- Persian
- Polish
- Portuguese
- Romanian
- Russian
- Sindhi
- Sinhala
- Somali
- Spanish
- Swahili
- Swedish
- Tagalog
- Tajik
- Tamil
- Tatar
- Telugu
- Thai
- Turkish
- Ukrainian
- Urdu
- Uyghur
- Uzbek
- Vietnamese
- Yao
All 114 surahs in Yoruba: the Qur’an in Yoruba.
Yoruba translation: Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni, from Quran.com. Transliteration: Quran.com. Recitation: Mishary Alafasy, from EveryAyah.com. MyDugsi is a learning aid, not a replacement for a qualified teacher.