Surah Al-Hujurat in Yoruba: translation and audio
Surah 49 · الحجرات · The Rooms · 18 verses
Surah Al-Hujurat verse by verse: the Arabic with a recitation you can repeat, the transliteration, and the Yoruba translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni. For the meaning of every word, see Surah Al-Hujurat word by word in English.
Verse 1
يَـٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُوا۟ لَا تُقَدِّمُوا۟ بَيْنَ يَدَىِ ٱللَّهِ وَرَسُولِهِۦ ۖ وَٱتَّقُوا۟ ٱللَّهَ ۚ إِنَّ ٱللَّهَ سَمِيعٌ عَلِيمٌ
Transliteration yāayyuhā alladhīna āmanū lā tuqaddimū bayna yadayi l-lahi warasūlihi wa-ittaqū l-laha inna l-laha samīʿun ʿalīmun
Yoruba Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ̀yin kò gbọdọ̀ gbawájú mọ́ Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀ lọ́wọ́. Kí ẹ sì bẹ̀rù Allāhu. Dájúdájú Allāhu ni Olùgbọ́, Onímọ̀.
Verse 2
يَـٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُوا۟ لَا تَرْفَعُوٓا۟ أَصْوَٰتَكُمْ فَوْقَ صَوْتِ ٱلنَّبِىِّ وَلَا تَجْهَرُوا۟ لَهُۥ بِٱلْقَوْلِ كَجَهْرِ بَعْضِكُمْ لِبَعْضٍ أَن تَحْبَطَ أَعْمَـٰلُكُمْ وَأَنتُمْ لَا تَشْعُرُونَ
Transliteration yāayyuhā alladhīna āmanū lā tarfaʿū aṣwātakum fawqa ṣawti l-nabiyi walā tajharū lahu bil-qawli kajahri baʿḍikum libaʿḍin an taḥbaṭa aʿmālukum wa-antum lā tashʿurūna
Yoruba Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ má ṣe gbé ohùn yín ga borí ohùn Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -. Kí ẹ sì má ṣe fi ohùn ariwo bá a sọ̀rọ̀ gẹ́gẹ́ bí apá kan yín ṣe ń fi ohùn ariwo bá apá kan sọ̀rọ̀ nítorí kí àwọn iṣẹ́ yín má baà bàjẹ́, ẹ̀yin kò sì níí fura.
Verse 3
إِنَّ ٱلَّذِينَ يَغُضُّونَ أَصْوَٰتَهُمْ عِندَ رَسُولِ ٱللَّهِ أُو۟لَـٰٓئِكَ ٱلَّذِينَ ٱمْتَحَنَ ٱللَّهُ قُلُوبَهُمْ لِلتَّقْوَىٰ ۚ لَهُم مَّغْفِرَةٌ وَأَجْرٌ عَظِيمٌ
Transliteration inna alladhīna yaghuḍḍūna aṣwātahum ʿinda rasūli l-lahi ulāika alladhīna im'taḥana l-lahu qulūbahum lilttaqwā lahum maghfiratun wa-ajrun ʿaẓīmun
Yoruba Dájúdájú àwọn tó ń rẹ ohùn wọn nílẹ̀ lọ́dọ̀ Òjíṣẹ́ Allāhu, àwọn wọ̀nyẹn ni àwọn tí Allāhu ti gbìdánwò ọkàn wọn fún ìbẹ̀rù (Rẹ̀). Àforíjìn àti ẹ̀san ńlá wà fún wọn.
Verse 4
إِنَّ ٱلَّذِينَ يُنَادُونَكَ مِن وَرَآءِ ٱلْحُجُرَٰتِ أَكْثَرُهُمْ لَا يَعْقِلُونَ
Transliteration inna alladhīna yunādūnaka min warāi l-ḥujurāti aktharuhum lā yaʿqilūna
Yoruba Dájúdájú àwọn tó ń pè ọ́ láti ẹ̀yìn àwọn yàrá ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn ni kò ṣe làákàyè.
Verse 5
وَلَوْ أَنَّهُمْ صَبَرُوا۟ حَتَّىٰ تَخْرُجَ إِلَيْهِمْ لَكَانَ خَيْرًا لَّهُمْ ۚ وَٱللَّهُ غَفُورٌ رَّحِيمٌ
Transliteration walaw annahum ṣabarū ḥattā takhruja ilayhim lakāna khayran lahum wal-lahu ghafūrun raḥīmun
Yoruba Tí ó bá jẹ́ pé dájúdájú wọ́n ṣe sùúrù títí o máa fi jáde sí wọn ni, ìbá dára jùlọ fún wọn. Allāhu sì ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.
Verse 6
يَـٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُوٓا۟ إِن جَآءَكُمْ فَاسِقٌۢ بِنَبَإٍ فَتَبَيَّنُوٓا۟ أَن تُصِيبُوا۟ قَوْمًۢا بِجَهَـٰلَةٍ فَتُصْبِحُوا۟ عَلَىٰ مَا فَعَلْتُمْ نَـٰدِمِينَ
Transliteration yāayyuhā alladhīna āmanū in jāakum fāsiqun binaba-in fatabayyanū an tuṣībū qawman bijahālatin fatuṣ'biḥū ʿalā mā faʿaltum nādimīna
Yoruba Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, tí arúfin kan bá mú ìró kan wá ba yín, ẹ ṣe pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ láti mọ òdodo (nípa ọ̀rọ̀ náà) nítorí kí ẹ má baà ṣe àwọn ènìyàn kan ní ṣùtá pẹ̀lú àìmọ̀, kí ẹ má baà di olùkábàámọ̀ lórí ohun tí ẹ ṣe.
Verse 7
وَٱعْلَمُوٓا۟ أَنَّ فِيكُمْ رَسُولَ ٱللَّهِ ۚ لَوْ يُطِيعُكُمْ فِى كَثِيرٍ مِّنَ ٱلْأَمْرِ لَعَنِتُّمْ وَلَـٰكِنَّ ٱللَّهَ حَبَّبَ إِلَيْكُمُ ٱلْإِيمَـٰنَ وَزَيَّنَهُۥ فِى قُلُوبِكُمْ وَكَرَّهَ إِلَيْكُمُ ٱلْكُفْرَ وَٱلْفُسُوقَ وَٱلْعِصْيَانَ ۚ أُو۟لَـٰٓئِكَ هُمُ ٱلرَّٰشِدُونَ
Transliteration wa-iʿ'lamū anna fīkum rasūla l-lahi law yuṭīʿukum fī kathīrin mina l-amri laʿanittum walākinna l-laha ḥabbaba ilaykumu l-īmāna wazayyanahu fī qulūbikum wakarraha ilaykumu l-kuf'ra wal-fusūqa wal-ʿiṣ'yāna ulāika humu l-rāshidūna
Yoruba Kí ẹ sì mọ̀ pé dájúdájú Òjíṣẹ́ Allāhu wà lààrin yín.Tí ó bá jẹ́ pé ó ń tẹ̀lé yín níbi ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ nínú ọ̀rọ̀ (tó ń ṣẹlẹ̀) ni, dájúdájú ẹ̀yin ìbá ti kó ara yín sínú wàhálà. Ṣùgbọ́n Allāhu jẹ́ kí ẹ nífẹ̀ẹ́ sí ìgbàgbọ́ òdodo. Ó ṣe é ní ọ̀ṣọ́ sínú ọkàn yín. Ó sì jẹ́ kí ẹ kórira àìgbàgbọ́, ìwà burúkú àti ìyapa àṣẹ. Àwọn wọ̀nyẹn ni àwọn olùmọ̀nà.
Verse 8
فَضْلًا مِّنَ ٱللَّهِ وَنِعْمَةً ۚ وَٱللَّهُ عَلِيمٌ حَكِيمٌ
Transliteration faḍlan mina l-lahi waniʿ'matan wal-lahu ʿalīmun ḥakīmun
Yoruba (Èyí jẹ́) oore àjùlọ àti ìdẹ̀ra láti ọ̀dọ̀ Allāhu. Allāhu sì ni Onímọ̀, Ọlọ́gbọ́n.
Verse 9
وَإِن طَآئِفَتَانِ مِنَ ٱلْمُؤْمِنِينَ ٱقْتَتَلُوا۟ فَأَصْلِحُوا۟ بَيْنَهُمَا ۖ فَإِنۢ بَغَتْ إِحْدَىٰهُمَا عَلَى ٱلْأُخْرَىٰ فَقَـٰتِلُوا۟ ٱلَّتِى تَبْغِى حَتَّىٰ تَفِىٓءَ إِلَىٰٓ أَمْرِ ٱللَّهِ ۚ فَإِن فَآءَتْ فَأَصْلِحُوا۟ بَيْنَهُمَا بِٱلْعَدْلِ وَأَقْسِطُوٓا۟ ۖ إِنَّ ٱللَّهَ يُحِبُّ ٱلْمُقْسِطِينَ
Transliteration wa-in ṭāifatāni mina l-mu'minīna iq'tatalū fa-aṣliḥū baynahumā fa-in baghat iḥ'dāhumā ʿalā l-ukh'rā faqātilū allatī tabghī ḥattā tafīa ilā amri l-lahi fa-in fāat fa-aṣliḥū baynahumā bil-ʿadli wa-aqsiṭū inna l-laha yuḥibbu l-muq'siṭīna
Yoruba Tí igun méjì nínú àwọn onígbàgbọ́ òdodo bá ń bá ara wọn jà, ẹ ṣe àtúnṣe láààrin àwọn méjèèjì. Tí ọ̀kan nínú àwọn méjèèjì bá sì kọjá ẹnu-ààlà lórí ìkejì, ẹ bá èyí tí ó kọjá ẹnu-ààlà jà títí ó fi máa ṣẹ́rí padà síbi àṣẹ Allāhu. Tí ó bá sì ṣẹ́rí padà, ẹ ṣe àtúnṣe láààrin àwọn méjèèjì pẹ̀lú déédé. Kí ẹ ṣe déédé. Dájúdájú Allāhu fẹ́ràn àwọn olùṣe- déédé.
Verse 10
إِنَّمَا ٱلْمُؤْمِنُونَ إِخْوَةٌ فَأَصْلِحُوا۟ بَيْنَ أَخَوَيْكُمْ ۚ وَٱتَّقُوا۟ ٱللَّهَ لَعَلَّكُمْ تُرْحَمُونَ
Transliteration innamā l-mu'minūna ikh'watun fa-aṣliḥū bayna akhawaykum wa-ittaqū l-laha laʿallakum tur'ḥamūna
Yoruba Ọmọ ìyá (ẹ̀sìn) ni àwọn onígbàgbọ́ òdodo. Nítorí náà, ẹ ṣàtúnṣe láààrin àwọn ọmọ ìyá yín méjèèjì. Kí ẹ sì bẹ̀rù Allāhu nítorí kí A lè kẹ yín.
Verse 11
يَـٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُوا۟ لَا يَسْخَرْ قَوْمٌ مِّن قَوْمٍ عَسَىٰٓ أَن يَكُونُوا۟ خَيْرًا مِّنْهُمْ وَلَا نِسَآءٌ مِّن نِّسَآءٍ عَسَىٰٓ أَن يَكُنَّ خَيْرًا مِّنْهُنَّ ۖ وَلَا تَلْمِزُوٓا۟ أَنفُسَكُمْ وَلَا تَنَابَزُوا۟ بِٱلْأَلْقَـٰبِ ۖ بِئْسَ ٱلِٱسْمُ ٱلْفُسُوقُ بَعْدَ ٱلْإِيمَـٰنِ ۚ وَمَن لَّمْ يَتُبْ فَأُو۟لَـٰٓئِكَ هُمُ ٱلظَّـٰلِمُونَ
Transliteration yāayyuhā alladhīna āmanū lā yaskhar qawmun min qawmin ʿasā an yakūnū khayran min'hum walā nisāon min nisāin ʿasā an yakunna khayran min'hunna walā talmizū anfusakum walā tanābazū bil-alqābi bi'sa l-s'mu l-fusūqu baʿda l-īmāni waman lam yatub fa-ulāika humu l-ẓālimūna
Yoruba Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, àwọn ènìyàn kan kò gbọ́dọ̀ fi àwọn ènìyàn kan ṣe yẹ̀yẹ́. Ó lè jẹ́ pé àwọn (tí wọ́n sọ di oníyẹ̀yẹ́) dára ju àwọn (tó ń ṣe yẹ̀yẹ́). Àwọn obìnrin kan (kò sì gbọ́dọ̀ fi) àwọn obìnrin kan (ṣe yẹ̀yẹ́). Ó lè jẹ́ pé àwọn (tí wọ́n sọ di oníyẹ̀yẹ́) dára ju àwọn (tó ń ṣe yẹ̀yẹ́). Ẹ má ṣe búra yín. Ẹ má pe’ra yín ní ìnagijẹ burúkú. Orúkọ burúkú (tí kò bá òfin ẹ̀sìn mu) burú lẹ́yìn ìgbàgbọ́ òdodo. Ẹnikẹ́ni tí kò bá ronú pìwàdà, àwọn wọ̀nyẹn gan-an ni alábòsí.
Verse 12
يَـٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُوا۟ ٱجْتَنِبُوا۟ كَثِيرًا مِّنَ ٱلظَّنِّ إِنَّ بَعْضَ ٱلظَّنِّ إِثْمٌ ۖ وَلَا تَجَسَّسُوا۟ وَلَا يَغْتَب بَّعْضُكُم بَعْضًا ۚ أَيُحِبُّ أَحَدُكُمْ أَن يَأْكُلَ لَحْمَ أَخِيهِ مَيْتًا فَكَرِهْتُمُوهُ ۚ وَٱتَّقُوا۟ ٱللَّهَ ۚ إِنَّ ٱللَّهَ تَوَّابٌ رَّحِيمٌ
Transliteration yāayyuhā alladhīna āmanū ij'tanibū kathīran mina l-ẓani inna baʿḍa l-ẓani ith'mun walā tajassasū walā yaghtab baʿḍukum baʿḍan ayuḥibbu aḥadukum an yakula laḥma akhīhi maytan fakarih'tumūhu wa-ittaqū l-laha inna l-laha tawwābun raḥīmun
Yoruba Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ jìnnà sí ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ àbá dídá. Dájúdájú ẹ̀ṣẹ̀ ni apá kan àbá dídá. Ẹ má ṣe tọpinpin ara yín. Kí apá kan yín má ṣe sọ̀rọ̀ apá kan lẹ́yìn. Ṣé ọ̀kan nínú yín nífẹ̀ẹ́ sí láti jẹ ẹran-ara ọmọ ìyá rẹ̀ ní òkú? Ẹ sì kórira rẹ̀. Ẹ bẹ̀rù Allāhu. Dájúdájú Allāhu ni Olùgba-ìronúpìwàdà, Àṣàkẹ́-ọ̀run.
Verse 13
يَـٰٓأَيُّهَا ٱلنَّاسُ إِنَّا خَلَقْنَـٰكُم مِّن ذَكَرٍ وَأُنثَىٰ وَجَعَلْنَـٰكُمْ شُعُوبًا وَقَبَآئِلَ لِتَعَارَفُوٓا۟ ۚ إِنَّ أَكْرَمَكُمْ عِندَ ٱللَّهِ أَتْقَىٰكُمْ ۚ إِنَّ ٱللَّهَ عَلِيمٌ خَبِيرٌ
Transliteration yāayyuhā l-nāsu innā khalaqnākum min dhakarin wa-unthā wajaʿalnākum shuʿūban waqabāila litaʿārafū inna akramakum ʿinda l-lahi atqākum inna l-laha ʿalīmun khabīrun
Yoruba Ẹ̀yin ènìyàn, dájúdájú Àwa ṣẹ̀dá yín láti ara ọkùnrin àti obìnrin. A sì ṣe yín ní orílẹ̀-èdè orílẹ̀-èdè àti ìran-ìran nítorí kí ẹ lè dára yín mọ̀. Dájúdájú alápọ̀n-ọ́nlé jùlọ nínú yín lọ́dọ̀ Allāhu ni ẹni tó bẹ̀rù (Rẹ̀) jùlọ. Dájúdájú Allāhu ni Onímọ̀, Alámọ̀tán.
Verse 14
۞ قَالَتِ ٱلْأَعْرَابُ ءَامَنَّا ۖ قُل لَّمْ تُؤْمِنُوا۟ وَلَـٰكِن قُولُوٓا۟ أَسْلَمْنَا وَلَمَّا يَدْخُلِ ٱلْإِيمَـٰنُ فِى قُلُوبِكُمْ ۖ وَإِن تُطِيعُوا۟ ٱللَّهَ وَرَسُولَهُۥ لَا يَلِتْكُم مِّنْ أَعْمَـٰلِكُمْ شَيْـًٔا ۚ إِنَّ ٱللَّهَ غَفُورٌ رَّحِيمٌ
Transliteration qālati l-aʿrābu āmannā qul lam tu'minū walākin qūlū aslamnā walammā yadkhuli l-īmānu fī qulūbikum wa-in tuṭīʿū l-laha warasūlahu lā yalit'kum min aʿmālikum shayan inna l-laha ghafūrun raḥīmun
Yoruba Àwọn Lárúbáwá oko sọ pé: “A gbàgbọ́ ní òdodo.” Sọ pé: “Ẹ̀yin kò gbàgbọ́ ní òdodo.” Ṣùgbọ́n ẹ sọ pé: “A gba ’Islām.” níwọ̀n ìgbà tí ìgbàgbọ́ òdodo kò tí ì wọ’nú ọkàn yín. Tí ẹ bá tẹ̀lé (àṣẹ) Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀, (Allāhu) kò níí dín kiní kan kù fún yín nínú (ẹ̀san) àwọn iṣẹ́ yín. Dájúdájú Allāhu ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.
Verse 15
إِنَّمَا ٱلْمُؤْمِنُونَ ٱلَّذِينَ ءَامَنُوا۟ بِٱللَّهِ وَرَسُولِهِۦ ثُمَّ لَمْ يَرْتَابُوا۟ وَجَـٰهَدُوا۟ بِأَمْوَٰلِهِمْ وَأَنفُسِهِمْ فِى سَبِيلِ ٱللَّهِ ۚ أُو۟لَـٰٓئِكَ هُمُ ٱلصَّـٰدِقُونَ
Transliteration innamā l-mu'minūna alladhīna āmanū bil-lahi warasūlihi thumma lam yartābū wajāhadū bi-amwālihim wa-anfusihim fī sabīli l-lahi ulāika humu l-ṣādiqūna
Yoruba Àwọn onígbàgbọ́ òdodo ni àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo nínú Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀, lẹ́yìn náà tí wọn kò ṣeyèméjì, tí wọ́n sì fi dúkìá wọn àti ẹ̀mí wọn jagun fún ẹ̀sìn Allāhu. Àwọn wọ̀nyẹn gan-an ni olódodo.
Verse 16
قُلْ أَتُعَلِّمُونَ ٱللَّهَ بِدِينِكُمْ وَٱللَّهُ يَعْلَمُ مَا فِى ٱلسَّمَـٰوَٰتِ وَمَا فِى ٱلْأَرْضِ ۚ وَٱللَّهُ بِكُلِّ شَىْءٍ عَلِيمٌ
Transliteration qul atuʿallimūna l-laha bidīnikum wal-lahu yaʿlamu mā fī l-samāwāti wamā fī l-arḍi wal-lahu bikulli shayin ʿalīmun
Yoruba Sọ pé: “Ṣé ẹ̀yin yóò máa sọ nípa ẹ̀sìn yín fún Allāhu ni (pé ìgbàgbọ́ òdodo ti wà nínú ọkàn yín)?” Allāhu sì mọ ohunkóhun tó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ohunkóhun tó wà nínú ilẹ̀. Allāhu sì ni Onímọ̀ nípa gbogbo n̄ǹkan.
Verse 17
يَمُنُّونَ عَلَيْكَ أَنْ أَسْلَمُوا۟ ۖ قُل لَّا تَمُنُّوا۟ عَلَىَّ إِسْلَـٰمَكُم ۖ بَلِ ٱللَّهُ يَمُنُّ عَلَيْكُمْ أَنْ هَدَىٰكُمْ لِلْإِيمَـٰنِ إِن كُنتُمْ صَـٰدِقِينَ
Transliteration yamunnūna ʿalayka an aslamū qul lā tamunnū ʿalayya is'lāmakum bali l-lahu yamunnu ʿalaykum an hadākum lil'īmāni in kuntum ṣādiqīna
Yoruba Wọ́n ń ṣèrègún lórí rẹ pé àwọn gba ’Islām. Sọ pé: “Ẹ má fi ’Islām yín ṣèrègún lórí mi. Bí kò ṣe pé Allāhu l’Ó máa ṣèrègún lórí yín pé Ó fi yín mọ̀nà síbi ìgbàgbọ́ òdodo tí ẹ bá jẹ́ olódodo.”
Verse 18
إِنَّ ٱللَّهَ يَعْلَمُ غَيْبَ ٱلسَّمَـٰوَٰتِ وَٱلْأَرْضِ ۚ وَٱللَّهُ بَصِيرٌۢ بِمَا تَعْمَلُونَ
Transliteration inna l-laha yaʿlamu ghayba l-samāwāti wal-arḍi wal-lahu baṣīrun bimā taʿmalūna
Yoruba Dájúdájú Allāhu mọ ìkọ̀kọ̀ àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Àti pé Allāhu ni Olùríran nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.
Read Surah Al-Hujurat in another language
- English (word by word)
- Albanian
- Amazigh
- Amharic
- Assamese
- Azerbaijani
- Bambara
- Bangla
- Bosnian
- Bulgarian
- Chechen
- Chinese
- Czech
- Dari
- Dhivehi
- Dutch
- Finnish
- French
- German
- Gujarati
- Hausa
- Hebrew
- Hindi
- Indonesian
- Italian
- Japanese
- Kannada
- Kazakh
- Khmer
- Kinyarwanda
- Korean
- Kurdish
- Luganda
- Malay
- Malayalam
- Maranao
- Marathi
- Nepali
- Norwegian
- Oromo
- Pashto
- Persian
- Polish
- Portuguese
- Romanian
- Russian
- Sindhi
- Sinhala
- Somali
- Spanish
- Swahili
- Swedish
- Tagalog
- Tajik
- Tamil
- Tatar
- Telugu
- Thai
- Turkish
- Ukrainian
- Urdu
- Uyghur
- Uzbek
- Vietnamese
- Yao
All 114 surahs in Yoruba: the Qur’an in Yoruba.
Yoruba translation: Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni, from Quran.com. Transliteration: Quran.com. Recitation: Mishary Alafasy, from EveryAyah.com. MyDugsi is a learning aid, not a replacement for a qualified teacher.