MyDugsiStart learning

Surah Nuh in Yoruba: translation and audio

Surah 71 · نوح · Noah · 28 verses

Surah Nuh verse by verse: the Arabic with a recitation you can repeat, the transliteration, and the Yoruba translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni. For the meaning of every word, see Surah Nuh word by word in English.

Verse 1

إِنَّآ أَرْسَلْنَا نُوحًا إِلَىٰ قَوْمِهِۦٓ أَنْ أَنذِرْ قَوْمَكَ مِن قَبْلِ أَن يَأْتِيَهُمْ عَذَابٌ أَلِيمٌ

Transliteration innā arsalnā nūḥan ilā qawmihi an andhir qawmaka min qabli an yatiyahum ʿadhābun alīmun

Yoruba Dájúdájú Àwa rán (Ànábì) Nūh níṣẹ́ sí ìjọ rẹ̀ pé: “Ṣèkìlọ̀ fún ìjọ rẹ ṣíwájú kí ìyà ẹlẹ́ta-eléro tó dé bá wọn.”

Verse 2

قَالَ يَـٰقَوْمِ إِنِّى لَكُمْ نَذِيرٌ مُّبِينٌ

Transliteration qāla yāqawmi innī lakum nadhīrun mubīnun

Yoruba Ó sọ pé: “Ẹ̀yin ìjọ mi, dájúdájú èmi ni olùkìlọ̀ pọ́nńbélé fún yín

Verse 3

أَنِ ٱعْبُدُوا۟ ٱللَّهَ وَٱتَّقُوهُ وَأَطِيعُونِ

Transliteration ani uʿ'budū l-laha wa-ittaqūhu wa-aṭīʿūni

Yoruba pé kí ẹ jọ́sìn fún Allāhu, kí ẹ bẹ̀rù Rẹ̀, kí ẹ sì tẹ̀lé mi.

Verse 4

يَغْفِرْ لَكُم مِّن ذُنُوبِكُمْ وَيُؤَخِّرْكُمْ إِلَىٰٓ أَجَلٍ مُّسَمًّى ۚ إِنَّ أَجَلَ ٱللَّهِ إِذَا جَآءَ لَا يُؤَخَّرُ ۖ لَوْ كُنتُمْ تَعْلَمُونَ

Transliteration yaghfir lakum min dhunūbikum wayu-akhir'kum ilā ajalin musamman inna ajala l-lahi idhā jāa lā yu-akharu law kuntum taʿlamūna

Yoruba (Allāhu) máa ṣàforíjìn àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín fún yín. Ó sì máa lọ yín lára títí di gbèdéke àkókò kan. Dájúdájú àkókò (ikú tí) Allāhu (kọ mọ́ ẹ̀dá), nígbà tí ó bá dé, wọn kò níí sún un ṣíwájú tí ó bá jẹ́ pé ẹ mọ̀.”

Verse 5

قَالَ رَبِّ إِنِّى دَعَوْتُ قَوْمِى لَيْلًا وَنَهَارًا

Transliteration qāla rabbi innī daʿawtu qawmī laylan wanahāran

Yoruba Ó sọ pé: “Olúwa mi, dájúdájú èmi pe ìjọ mi ní òru àti ní ọ̀sán.

Verse 6

فَلَمْ يَزِدْهُمْ دُعَآءِىٓ إِلَّا فِرَارًا

Transliteration falam yazid'hum duʿāī illā firāran

Yoruba Ìpè mi kò sì ṣe àlékún kan fún wọn àyàfi sísá sẹ́yìn (fún òdodo).

Verse 7

وَإِنِّى كُلَّمَا دَعَوْتُهُمْ لِتَغْفِرَ لَهُمْ جَعَلُوٓا۟ أَصَـٰبِعَهُمْ فِىٓ ءَاذَانِهِمْ وَٱسْتَغْشَوْا۟ ثِيَابَهُمْ وَأَصَرُّوا۟ وَٱسْتَكْبَرُوا۟ ٱسْتِكْبَارًا

Transliteration wa-innī kullamā daʿawtuhum litaghfira lahum jaʿalū aṣābiʿahum fī ādhānihim wa-is'taghshaw thiyābahum wa-aṣarrū wa-is'takbarū is'tik'bāran

Yoruba Àti pé ìgbàkígbà tí mo bá pè wọ́n pé kí O lè foríjìn wọ́n, wọ́n ń fi ọmọníka wọn dí etí wọn, wọ́n ń yíṣọ wọn borí, wọ́n ń takú (sórí ẹ̀ṣẹ̀), wọ́n sì ń ṣègbéraga gan-an.

Verse 8

ثُمَّ إِنِّى دَعَوْتُهُمْ جِهَارًا

Transliteration thumma innī daʿawtuhum jihāran

Yoruba Lẹ́yìn náà, dájúdájú èmi pè wọ́n pẹ̀lú ohùn òkè.

Verse 9

ثُمَّ إِنِّىٓ أَعْلَنتُ لَهُمْ وَأَسْرَرْتُ لَهُمْ إِسْرَارًا

Transliteration thumma innī aʿlantu lahum wa-asrartu lahum is'rāran

Yoruba Lẹ́yìn náà, dájúdájú èmi kéde fún wọn, mo sì tún pè wọ́n ní ìdá kọ́ńkọ́.

Verse 10

فَقُلْتُ ٱسْتَغْفِرُوا۟ رَبَّكُمْ إِنَّهُۥ كَانَ غَفَّارًا

Transliteration faqul'tu is'taghfirū rabbakum innahu kāna ghaffāran

Yoruba Mo sì sọ pé, ẹ tọrọ àforíjìn ní ọ̀dọ̀ Olúwa yín, dájúdájú Ó ń jẹ́ Aláforíjìn.

Verse 11

يُرْسِلِ ٱلسَّمَآءَ عَلَيْكُم مِّدْرَارًا

Transliteration yur'sili l-samāa ʿalaykum mid'rāran

Yoruba Ó máa rọ̀jò fún yín ní òjò púpọ̀,

Verse 12

وَيُمْدِدْكُم بِأَمْوَٰلٍ وَبَنِينَ وَيَجْعَل لَّكُمْ جَنَّـٰتٍ وَيَجْعَل لَّكُمْ أَنْهَـٰرًا

Transliteration wayum'did'kum bi-amwālin wabanīna wayajʿal lakum jannātin wayajʿal lakum anhāran

Yoruba Ó máa fi àwọn dúkìá àti àwọn ọmọkùnrin ràn yín lọ́wọ́. Ó máa ṣe àwọn ọgbà oko fún yín. Ó sì máa ṣe àwọn odò fún yín.

Verse 13

مَّا لَكُمْ لَا تَرْجُونَ لِلَّهِ وَقَارًا

Transliteration mā lakum lā tarjūna lillahi waqāran

Yoruba Kí ló mu yín tí ẹ kò páyà títóbi Allāhu?

Verse 14

وَقَدْ خَلَقَكُمْ أَطْوَارًا

Transliteration waqad khalaqakum aṭwāran

Yoruba Ó sì kúkú ṣẹ̀dá yín láti ìrísí kan sí òmíràn (nínú oyún).1

Verse 15

أَلَمْ تَرَوْا۟ كَيْفَ خَلَقَ ٱللَّهُ سَبْعَ سَمَـٰوَٰتٍ طِبَاقًا

Transliteration alam taraw kayfa khalaqa l-lahu sabʿa samāwātin ṭibāqan

Yoruba Ṣé ẹ kò wòye sí bí Allāhu ṣe dá àwọn sánmọ̀ méje ní ìpele ìpele ni?

Verse 16

وَجَعَلَ ٱلْقَمَرَ فِيهِنَّ نُورًا وَجَعَلَ ٱلشَّمْسَ سِرَاجًا

Transliteration wajaʿala l-qamara fīhinna nūran wajaʿala l-shamsa sirājan

Yoruba Ó sì ṣe òṣùpá ní ìmọ́lẹ̀ sínú wọn. Ó tún ṣe òòrùn ní àtùpà.

Verse 17

وَٱللَّهُ أَنۢبَتَكُم مِّنَ ٱلْأَرْضِ نَبَاتًا

Transliteration wal-lahu anbatakum mina l-arḍi nabātan

Yoruba Allāhu mu yín jáde láti ara erùpẹ̀ ilẹ̀.

Verse 18

ثُمَّ يُعِيدُكُمْ فِيهَا وَيُخْرِجُكُمْ إِخْرَاجًا

Transliteration thumma yuʿīdukum fīhā wayukh'rijukum ikh'rājan

Yoruba Lẹ́yìn náà, Ó máa da yín padà sínú rẹ̀. Ó sì máa mu yín jáde tààrà.

Verse 19

وَٱللَّهُ جَعَلَ لَكُمُ ٱلْأَرْضَ بِسَاطًا

Transliteration wal-lahu jaʿala lakumu l-arḍa bisāṭan

Yoruba Allāhu ṣe ilẹ̀ fún yín ní ìtẹ́

Verse 20

لِّتَسْلُكُوا۟ مِنْهَا سُبُلًا فِجَاجًا

Transliteration litaslukū min'hā subulan fijājan

Yoruba nítorí kí ẹ lè tọ àwọn ojú ọ̀nà fífẹ̀ gbẹ̀gẹ̀dẹ̀ lórí rẹ̀.”

Verse 21

قَالَ نُوحٌ رَّبِّ إِنَّهُمْ عَصَوْنِى وَٱتَّبَعُوا۟ مَن لَّمْ يَزِدْهُ مَالُهُۥ وَوَلَدُهُۥٓ إِلَّا خَسَارًا

Transliteration qāla nūḥun rabbi innahum ʿaṣawnī wa-ittabaʿū man lam yazid'hu māluhu wawaladuhu illā khasāran

Yoruba (Ànábì) Nūh sọ pé: “Olúwa mi, dájúdájú wọ́n yapa mi. Wọ́n sì tẹ̀lé ẹni tí dúkìá rẹ̀ àti ọmọ rẹ̀ kò ṣe àlékún kan fún bí kò ṣe òfò.

Verse 22

وَمَكَرُوا۟ مَكْرًا كُبَّارًا

Transliteration wamakarū makran kubbāran

Yoruba Wọ́n sì déte ní ète tó tóbi.”

Verse 23

وَقَالُوا۟ لَا تَذَرُنَّ ءَالِهَتَكُمْ وَلَا تَذَرُنَّ وَدًّا وَلَا سُوَاعًا وَلَا يَغُوثَ وَيَعُوقَ وَنَسْرًا

Transliteration waqālū lā tadharunna ālihatakum walā tadharunna waddan walā suwāʿan walā yaghūtha wayaʿūqa wanasran

Yoruba Wọ́n sì wí pé: “Ẹ kò gbọ́dọ̀ fi àwọn òrìṣà yín sílẹ̀. Ẹ kò gbọ́dọ̀ fi òrìṣà Wadd, Suwā‘u, Yẹgūth, Yẹ‘ūƙ àti Nasr sílẹ̀.”

Verse 24

وَقَدْ أَضَلُّوا۟ كَثِيرًا ۖ وَلَا تَزِدِ ٱلظَّـٰلِمِينَ إِلَّا ضَلَـٰلًا

Transliteration waqad aḍallū kathīran walā tazidi l-ẓālimīna illā ḍalālan

Yoruba Dájúdájú wọ́n ti kó ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ṣìnà. (Olúwa mi) má ṣe jẹ́ kí àwọn alábòsí lékún ní kiní kan bí kò ṣe ìṣìnà.

Verse 25

مِّمَّا خَطِيٓـَٔـٰتِهِمْ أُغْرِقُوا۟ فَأُدْخِلُوا۟ نَارًا فَلَمْ يَجِدُوا۟ لَهُم مِّن دُونِ ٱللَّهِ أَنصَارًا

Transliteration mimmā khaṭīātihim ugh'riqū fa-ud'khilū nāran falam yajidū lahum min dūni l-lahi anṣāran

Yoruba Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn, wọ́n tẹ̀ wọ́n rì sínú omi. Wọ́n sì máa fi wọ́n sínú Iná. Wọn kò sì níí rí àwọn alárànṣe kan fún wọn lẹ́yìn Allāhu.

Verse 26

وَقَالَ نُوحٌ رَّبِّ لَا تَذَرْ عَلَى ٱلْأَرْضِ مِنَ ٱلْكَـٰفِرِينَ دَيَّارًا

Transliteration waqāla nūḥun rabbi lā tadhar ʿalā l-arḍi mina l-kāfirīna dayyāran

Yoruba (Ànábì) Nūh tún sọ pé: “Olúwa mi, má ṣe fi ẹnì kan kan nínú àwọn aláìgbàgbọ́ sílẹ̀ lórí ilẹ̀.

Verse 27

إِنَّكَ إِن تَذَرْهُمْ يُضِلُّوا۟ عِبَادَكَ وَلَا يَلِدُوٓا۟ إِلَّا فَاجِرًا كَفَّارًا

Transliteration innaka in tadharhum yuḍillū ʿibādaka walā yalidū illā fājiran kaffāran

Yoruba Dájúdájú tí Ìwọ bá fi wọ́n sílẹ̀, wọn yóò kó ìṣìnà bá àwọn ẹrú Rẹ. Wọn kò sì níí bí ọmọ kan àfi ẹni burúkú, aláìgbàgbọ́.

Verse 28

رَّبِّ ٱغْفِرْ لِى وَلِوَٰلِدَىَّ وَلِمَن دَخَلَ بَيْتِىَ مُؤْمِنًا وَلِلْمُؤْمِنِينَ وَٱلْمُؤْمِنَـٰتِ وَلَا تَزِدِ ٱلظَّـٰلِمِينَ إِلَّا تَبَارًۢا

Transliteration rabbi igh'fir lī waliwālidayya waliman dakhala baytiya mu'minan walil'mu'minīna wal-mu'mināti walā tazidi l-ẓālimīna illā tabāran

Yoruba Olúwa mi foríjìn èmi, àwọn òbí mi méjèèjì àti ẹni tó bá wọ inú ilé mi (tí ó jẹ́) onígbàgbọ́ òdodo àti àwọn onígbàgbọ́ òdodo lọ́kùnrin àti onígbàgbọ́ òdodo lóbìnrin. Má sì ṣàlékún kan fún àwọn alábòsí àfi ìparun.”

Read Surah Nuh in another language

All languages

All 114 surahs in Yoruba: the Qur’an in Yoruba.

Learn it in MyDugsi

Yoruba translation: Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni, from Quran.com. Transliteration: Quran.com. Recitation: Mishary Alafasy, from EveryAyah.com. MyDugsi is a learning aid, not a replacement for a qualified teacher.