MyDugsiStart learning

Surah Fatir in Yoruba: translation and audio

Surah 35 · فاطر · Originator · 45 verses

Surah Fatir verse by verse: the Arabic with a recitation you can repeat, the transliteration, and the Yoruba translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni. For the meaning of every word, see Surah Fatir word by word in English.

Verse 1

ٱلْحَمْدُ لِلَّهِ فَاطِرِ ٱلسَّمَـٰوَٰتِ وَٱلْأَرْضِ جَاعِلِ ٱلْمَلَـٰٓئِكَةِ رُسُلًا أُو۟لِىٓ أَجْنِحَةٍ مَّثْنَىٰ وَثُلَـٰثَ وَرُبَـٰعَ ۚ يَزِيدُ فِى ٱلْخَلْقِ مَا يَشَآءُ ۚ إِنَّ ٱللَّهَ عَلَىٰ كُلِّ شَىْءٍ قَدِيرٌ

Transliteration al-ḥamdu lillahi fāṭiri l-samāwāti wal-arḍi jāʿili l-malāikati rusulan ulī ajniḥatin mathnā wathulātha warubāʿa yazīdu fī l-khalqi mā yashāu inna l-laha ʿalā kulli shayin qadīrun

Yoruba Gbogbo ẹyìn ń jẹ́ ti Allāhu, Olùpilẹ̀dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀, (Ẹni tí) Ó ṣe àwọn mọlāika alápá méjì àti mẹ́ta àti mẹ́rin ní Òjíṣẹ́. Ó ń ṣe àlékún ohun tí Ó bá fẹ́ lára ẹ̀dá. Dájúdájú Allāhu ni Alágbára lórí gbogbo n̄ǹkan.1

Verse 2

مَّا يَفْتَحِ ٱللَّهُ لِلنَّاسِ مِن رَّحْمَةٍ فَلَا مُمْسِكَ لَهَا ۖ وَمَا يُمْسِكْ فَلَا مُرْسِلَ لَهُۥ مِنۢ بَعْدِهِۦ ۚ وَهُوَ ٱلْعَزِيزُ ٱلْحَكِيمُ

Transliteration mā yaftaḥi l-lahu lilnnāsi min raḥmatin falā mum'sika lahā wamā yum'sik falā mur'sila lahu min baʿdihi wahuwa l-ʿazīzu l-ḥakīmu

Yoruba Ohunkóhun tí Allāhu bá ṣí ọ̀nà rẹ̀ sílẹ̀ nínú ìkẹ́ fún àwọn ènìyàn, kò sí ẹni tí ó lè dì í mọ́wọ́ (láti dá a dúró). Ohunkóhun tí Ó bá sì mú dání, kò sí ẹni tí ó lè mú un wá lẹ́yìn Rẹ̀. Òun sì ni Alágbára, Ọlọ́gbọ́n.

Verse 3

يَـٰٓأَيُّهَا ٱلنَّاسُ ٱذْكُرُوا۟ نِعْمَتَ ٱللَّهِ عَلَيْكُمْ ۚ هَلْ مِنْ خَـٰلِقٍ غَيْرُ ٱللَّهِ يَرْزُقُكُم مِّنَ ٱلسَّمَآءِ وَٱلْأَرْضِ ۚ لَآ إِلَـٰهَ إِلَّا هُوَ ۖ فَأَنَّىٰ تُؤْفَكُونَ

Transliteration yāayyuhā l-nāsu udh'kurū niʿ'mata l-lahi ʿalaykum hal min khāliqin ghayru l-lahi yarzuqukum mina l-samāi wal-arḍi lā ilāha illā huwa fa-annā tu'fakūna

Yoruba Ẹ̀yin ènìyàn, ẹ rántí ìdẹ̀ra Allāhu lórí yín. Ǹjẹ́ ẹ̀lẹ́dàá kan yàtọ̀ sí Allāhu tún wà tí ó ń pèsè fún yín láti inú sánmọ̀ àti ilẹ̀? Kò sí ọlọ́hun kan tí a gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo àyàfi Òun. Nítorí náà, báwo ni wọ́n ṣe ń ṣẹ yín lórí kúrò níbi òdodo?

Verse 4

وَإِن يُكَذِّبُوكَ فَقَدْ كُذِّبَتْ رُسُلٌ مِّن قَبْلِكَ ۚ وَإِلَى ٱللَّهِ تُرْجَعُ ٱلْأُمُورُ

Transliteration wa-in yukadhibūka faqad kudhibat rusulun min qablika wa-ilā l-lahi tur'jaʿu l-umūru

Yoruba Tí wọ́n bá pè ọ́ ní òpùrọ́, wọ́n kúkú ti pe àwọn Òjíṣẹ́ kan ní òpùrọ́ ṣíwájú rẹ. Ọ̀dọ̀ Allāhu sì ni wọ́n máa ṣẹ́rí àwọn ọ̀rọ̀ ẹ̀dá padà sí.

Verse 5

يَـٰٓأَيُّهَا ٱلنَّاسُ إِنَّ وَعْدَ ٱللَّهِ حَقٌّ ۖ فَلَا تَغُرَّنَّكُمُ ٱلْحَيَوٰةُ ٱلدُّنْيَا ۖ وَلَا يَغُرَّنَّكُم بِٱللَّهِ ٱلْغَرُورُ

Transliteration yāayyuhā l-nāsu inna waʿda l-lahi ḥaqqun falā taghurrannakumu l-ḥayatu l-dun'yā walā yaghurrannakum bil-lahi l-gharūru

Yoruba Ẹ̀yin ènìyàn, dájúdájú àdéhùn Allāhu ni òdodo. Ẹ má ṣe jẹ́ kí ìṣẹ̀mí ayé tàn yín jẹ. Kí ẹ sì má ṣe jẹ́ kí (Èṣù) ẹlẹ́tàn tàn yín jẹ.

Verse 6

إِنَّ ٱلشَّيْطَـٰنَ لَكُمْ عَدُوٌّ فَٱتَّخِذُوهُ عَدُوًّا ۚ إِنَّمَا يَدْعُوا۟ حِزْبَهُۥ لِيَكُونُوا۟ مِنْ أَصْحَـٰبِ ٱلسَّعِيرِ

Transliteration inna l-shayṭāna lakum ʿaduwwun fa-ittakhidhūhu ʿaduwwan innamā yadʿū ḥiz'bahu liyakūnū min aṣḥābi l-saʿīri

Yoruba Dájúdájú Èṣù ni ọ̀tá fún yín. Nítorí náà, ẹ mú un ní ọ̀tá. Ó kàn ń pe àwọn ìjọ rẹ̀ nítorí kí wọ́n lè jẹ́ èrò inú Iná tó ń jó.

Verse 7

ٱلَّذِينَ كَفَرُوا۟ لَهُمْ عَذَابٌ شَدِيدٌ ۖ وَٱلَّذِينَ ءَامَنُوا۟ وَعَمِلُوا۟ ٱلصَّـٰلِحَـٰتِ لَهُم مَّغْفِرَةٌ وَأَجْرٌ كَبِيرٌ

Transliteration alladhīna kafarū lahum ʿadhābun shadīdun wa-alladhīna āmanū waʿamilū l-ṣāliḥāti lahum maghfiratun wa-ajrun kabīrun

Yoruba Àwọn tó ṣàì gbàgbọ́, ìyà líle ń bẹ fún wọn. Àwọn tó sì gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n ṣe iṣẹ́ rere, àforíjìn àti ẹ̀san tó tóbi ń bẹ fún wọn.

Verse 8

أَفَمَن زُيِّنَ لَهُۥ سُوٓءُ عَمَلِهِۦ فَرَءَاهُ حَسَنًا ۖ فَإِنَّ ٱللَّهَ يُضِلُّ مَن يَشَآءُ وَيَهْدِى مَن يَشَآءُ ۖ فَلَا تَذْهَبْ نَفْسُكَ عَلَيْهِمْ حَسَرَٰتٍ ۚ إِنَّ ٱللَّهَ عَلِيمٌۢ بِمَا يَصْنَعُونَ

Transliteration afaman zuyyina lahu sūu ʿamalihi faraāhu ḥasanan fa-inna l-laha yuḍillu man yashāu wayahdī man yashāu falā tadhhab nafsuka ʿalayhim ḥasarātin inna l-laha ʿalīmun bimā yaṣnaʿūna

Yoruba Ṣé ẹni tí wọ́n ṣe iṣẹ́ aburú ọwọ́ rẹ̀ ní ọ̀ṣọ́ fún, tí ó sì ń rí i ní (iṣẹ́) dáadáa, (l’o fẹ́ máa banújẹ́ nítorí rẹ̀?) Dájúdájú Allāhu ń ṣi ẹni tí Ó bá fẹ́ lọ́nà. Ó sì ń fi ọ̀nà mọ ẹni tí Ó bá fẹ́. Nítorí náà, má ṣe fi ìbanújẹ́ pa ara rẹ̀ nítorí tiwọn. Dájúdájú Allāhu ni Onímọ̀ nípa ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́.

Verse 9

وَٱللَّهُ ٱلَّذِىٓ أَرْسَلَ ٱلرِّيَـٰحَ فَتُثِيرُ سَحَابًا فَسُقْنَـٰهُ إِلَىٰ بَلَدٍ مَّيِّتٍ فَأَحْيَيْنَا بِهِ ٱلْأَرْضَ بَعْدَ مَوْتِهَا ۚ كَذَٰلِكَ ٱلنُّشُورُ

Transliteration wal-lahu alladhī arsala l-riyāḥa fatuthīru saḥāban fasuq'nāhu ilā baladin mayyitin fa-aḥyaynā bihi l-arḍa baʿda mawtihā kadhālika l-nushūru

Yoruba Allāhu ni Ẹni tí Ó fi àwọn atẹ́gùn ránṣẹ́. (Atẹ́gùn náà) sì máa tú ẹ̀ṣújò sókè. A sì fi fún ìlú (tí ilẹ̀ rẹ̀) ti kú lómi mu. A sì fi ta ilẹ̀ náà jí lẹ́yìn tí ó ti kú. Báyẹn ni àjíǹde (ẹ̀dá yó ṣe rí).

Verse 10

مَن كَانَ يُرِيدُ ٱلْعِزَّةَ فَلِلَّهِ ٱلْعِزَّةُ جَمِيعًا ۚ إِلَيْهِ يَصْعَدُ ٱلْكَلِمُ ٱلطَّيِّبُ وَٱلْعَمَلُ ٱلصَّـٰلِحُ يَرْفَعُهُۥ ۚ وَٱلَّذِينَ يَمْكُرُونَ ٱلسَّيِّـَٔاتِ لَهُمْ عَذَابٌ شَدِيدٌ ۖ وَمَكْرُ أُو۟لَـٰٓئِكَ هُوَ يَبُورُ

Transliteration man kāna yurīdu l-ʿizata falillahi l-ʿizatu jamīʿan ilayhi yaṣʿadu l-kalimu l-ṭayibu wal-ʿamalu l-ṣāliḥu yarfaʿuhu wa-alladhīna yamkurūna l-sayiāti lahum ʿadhābun shadīdun wamakru ulāika huwa yabūru

Yoruba Ẹní tí ó bá ń fẹ́ iyì dájúdájú ti Allāhu ni gbogbo iyì pátápátá. Ọ̀dọ̀ Rẹ̀ ni ọ̀rọ̀ dáadáa ń gòkè lọ. Ó sì ń gbé iṣẹ́ rere gòkè (sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀). Àwọn tí wọ́n ń pète àwọn aburú, ìyà líle ń bẹ fún wọn. Ète àwọn wọ̀nyẹn sì máa parun.

Verse 11

وَٱللَّهُ خَلَقَكُم مِّن تُرَابٍ ثُمَّ مِن نُّطْفَةٍ ثُمَّ جَعَلَكُمْ أَزْوَٰجًا ۚ وَمَا تَحْمِلُ مِنْ أُنثَىٰ وَلَا تَضَعُ إِلَّا بِعِلْمِهِۦ ۚ وَمَا يُعَمَّرُ مِن مُّعَمَّرٍ وَلَا يُنقَصُ مِنْ عُمُرِهِۦٓ إِلَّا فِى كِتَـٰبٍ ۚ إِنَّ ذَٰلِكَ عَلَى ٱللَّهِ يَسِيرٌ

Transliteration wal-lahu khalaqakum min turābin thumma min nuṭ'fatin thumma jaʿalakum azwājan wamā taḥmilu min unthā walā taḍaʿu illā biʿil'mihi wamā yuʿammaru min muʿammarin walā yunqaṣu min ʿumurihi illā fī kitābin inna dhālika ʿalā l-lahi yasīrun

Yoruba Allāhu da yín láti ara erùpẹ̀. Lẹ́yìn náà, (Ó tún da yín) láti ara àtọ̀. Lẹ́yìn náà, Ó ṣe yín ní akọ-abo. Obìnrin kan kò níí lóyún, kò sì níí bímọ àfi pẹ̀lú ìmọ̀ Rẹ̀. Àti pé A kò níí fa ẹ̀mí ẹlẹ́mìí-gígùn gùn, A kò sì ní ṣe àdínkù nínú ọjọ́ orí (ẹlòmíìràn), àfi kí ó ti wà nínú tírà kan. Dájúdájú ìyẹn rọrùn fún Allāhu.

Verse 12

وَمَا يَسْتَوِى ٱلْبَحْرَانِ هَـٰذَا عَذْبٌ فُرَاتٌ سَآئِغٌ شَرَابُهُۥ وَهَـٰذَا مِلْحٌ أُجَاجٌ ۖ وَمِن كُلٍّ تَأْكُلُونَ لَحْمًا طَرِيًّا وَتَسْتَخْرِجُونَ حِلْيَةً تَلْبَسُونَهَا ۖ وَتَرَى ٱلْفُلْكَ فِيهِ مَوَاخِرَ لِتَبْتَغُوا۟ مِن فَضْلِهِۦ وَلَعَلَّكُمْ تَشْكُرُونَ

Transliteration wamā yastawī l-baḥrāni hādhā ʿadhbun furātun sāighun sharābuhu wahādhā mil'ḥun ujājun wamin kullin takulūna laḥman ṭariyyan watastakhrijūna ḥil'yatan talbasūnahā watarā l-ful'ka fīhi mawākhira litabtaghū min faḍlihi walaʿallakum tashkurūna

Yoruba Àwọn odò méjì náà kò dọ́gba; èyí ni (omi) dídùn gan-an, tí mímu rẹ̀ ń lọ tìnrín ní ọ̀fun. Èyí sì ni (omi) iyọ̀ tó móró. Àti pé nínú gbogbo (omi odò wọ̀nyí) l’ẹ ti ń jẹ ẹran (odò àti ẹja) tútù. Ẹ sì ń wa kùsà àwọn ohun ọ̀ṣọ́ tí ẹ̀ ń wọ̀ (sára). O sì ń rí àwọn ọkọ̀ ojú-omi tó ń la ààrin omi kọjá nítorí kí ẹ lè wá nínú oore Allāhu àti nítorí kí ẹ lè dúpẹ́ (fún Un).

Verse 13

يُولِجُ ٱلَّيْلَ فِى ٱلنَّهَارِ وَيُولِجُ ٱلنَّهَارَ فِى ٱلَّيْلِ وَسَخَّرَ ٱلشَّمْسَ وَٱلْقَمَرَ كُلٌّ يَجْرِى لِأَجَلٍ مُّسَمًّى ۚ ذَٰلِكُمُ ٱللَّهُ رَبُّكُمْ لَهُ ٱلْمُلْكُ ۚ وَٱلَّذِينَ تَدْعُونَ مِن دُونِهِۦ مَا يَمْلِكُونَ مِن قِطْمِيرٍ

Transliteration yūliju al-layla fī l-nahāri wayūliju l-nahāra fī al-layli wasakhara l-shamsa wal-qamara kullun yajrī li-ajalin musamman dhālikumu l-lahu rabbukum lahu l-mul'ku wa-alladhīna tadʿūna min dūnihi mā yamlikūna min qiṭ'mīrin

Yoruba (Allāhu) ń ti òru bọ inú ọ̀sán. Ó sì ń ti ọ̀sán bọ inú òru. Ó rọ òòrùn àti òṣùpá; ìkọ̀ọ̀kan wọn máa rìn fún gbèdéke àkókò kan.Ìyẹn ni Allāhu, Olúwa yín. TiRẹ̀ ni ìjọba. Àwọn tí ẹ sì ń pè lẹ́yìn Rẹ̀, wọn kò ní ìkápá kan lórí èpo kóró inú dàbínù.

Verse 14

إِن تَدْعُوهُمْ لَا يَسْمَعُوا۟ دُعَآءَكُمْ وَلَوْ سَمِعُوا۟ مَا ٱسْتَجَابُوا۟ لَكُمْ ۖ وَيَوْمَ ٱلْقِيَـٰمَةِ يَكْفُرُونَ بِشِرْكِكُمْ ۚ وَلَا يُنَبِّئُكَ مِثْلُ خَبِيرٍ

Transliteration in tadʿūhum lā yasmaʿū duʿāakum walaw samiʿū mā is'tajābū lakum wayawma l-qiyāmati yakfurūna bishir'kikum walā yunabbi-uka mith'lu khabīrin

Yoruba Tí ẹ bá pè wọ́n, wọn kò lè gbọ́ ìpè yín. Tí ó bá sì jẹ́ pé wọ́n gbọ́, wọn kò lè da yín lóhùn. Àti pé ní Ọjọ́ Àjíǹde, wọn yóò tako bí ẹ ṣe fi wọ́n ṣe akẹgbẹ́ fún Allāhu. Kò sì sí ẹni tí ó lè fún ọ ní ìró kan (nípa ẹ̀dá ju) irú (ìró tí) Onímọ̀-ìkọ̀kọ̀ (fún ọ nípa wọn).

Verse 15

۞ يَـٰٓأَيُّهَا ٱلنَّاسُ أَنتُمُ ٱلْفُقَرَآءُ إِلَى ٱللَّهِ ۖ وَٱللَّهُ هُوَ ٱلْغَنِىُّ ٱلْحَمِيدُ

Transliteration yāayyuhā l-nāsu antumu l-fuqarāu ilā l-lahi wal-lahu huwa l-ghaniyu l-ḥamīdu

Yoruba Ẹ̀yin ènìyàn, ẹ̀yin ni aláìní (tí ẹ ní bùkátà) sí Allāhu. Allāhu, Òun ni Ọlọ́rọ̀, Ẹlẹ́yìn.

Verse 16

إِن يَشَأْ يُذْهِبْكُمْ وَيَأْتِ بِخَلْقٍ جَدِيدٍ

Transliteration in yasha yudh'hib'kum wayati bikhalqin jadīdin

Yoruba Tí Ó bá fẹ́, Ó máa mu yín kúrò lórí ilẹ̀. Ó sì máa mú ẹ̀dá titun wá.

Verse 17

وَمَا ذَٰلِكَ عَلَى ٱللَّهِ بِعَزِيزٍ

Transliteration wamā dhālika ʿalā l-lahi biʿazīzin

Yoruba Ìyẹn kò sì lágbara kan lára Allāhu.1

Verse 18

وَلَا تَزِرُ وَازِرَةٌ وِزْرَ أُخْرَىٰ ۚ وَإِن تَدْعُ مُثْقَلَةٌ إِلَىٰ حِمْلِهَا لَا يُحْمَلْ مِنْهُ شَىْءٌ وَلَوْ كَانَ ذَا قُرْبَىٰٓ ۗ إِنَّمَا تُنذِرُ ٱلَّذِينَ يَخْشَوْنَ رَبَّهُم بِٱلْغَيْبِ وَأَقَامُوا۟ ٱلصَّلَوٰةَ ۚ وَمَن تَزَكَّىٰ فَإِنَّمَا يَتَزَكَّىٰ لِنَفْسِهِۦ ۚ وَإِلَى ٱللَّهِ ٱلْمَصِيرُ

Transliteration walā taziru wāziratun wiz'ra ukh'rā wa-in tadʿu muth'qalatun ilā ḥim'lihā lā yuḥ'mal min'hu shayon walaw kāna dhā qur'bā innamā tundhiru alladhīna yakhshawna rabbahum bil-ghaybi wa-aqāmū l-ṣalata waman tazakkā fa-innamā yatazakkā linafsihi wa-ilā l-lahi l-maṣīru

Yoruba Ẹlẹ́rù ẹ̀ṣẹ̀ kan kò níí ru ẹrù ẹ̀ṣẹ̀ ẹlòmíìràn. Kódà kí ẹnì kan tí ẹrù ẹ̀ṣẹ̀ wọ̀ lọ́rùn ké sí (ẹlòmíìràn) fún àbárù ẹrù ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, wọn kò níí bá a ru kiní kan nínú rẹ̀, ìbáà jẹ́ ìbátan.Àwọn tí ò ń ṣèkìlọ̀ fún ni àwọn tó ń páyà Olúwa wọn ní ìkọ̀kọ̀, tí wọ́n sì ń kírun. Ẹni tí ó bá ṣàfọ̀mọ́ (ara rẹ̀ kúrò nínú ìwà ẹ̀ṣẹ̀), ó ṣàfọ̀mọ́ fún ẹ̀mí ara rẹ̀ ni. Ọ̀dọ̀ Allāhu sì ni àbọ̀ ẹ̀dá.

Verse 19

وَمَا يَسْتَوِى ٱلْأَعْمَىٰ وَٱلْبَصِيرُ

Transliteration wamā yastawī l-aʿmā wal-baṣīru

Yoruba Afọ́jú àti olùríran kò dọ́gba.

Verse 20

وَلَا ٱلظُّلُمَـٰتُ وَلَا ٱلنُّورُ

Transliteration walā l-ẓulumātu walā l-nūru

Yoruba Àwọn òkùnkùn àti ìmọ́lẹ̀ (kò dọ́gba).

Verse 21

وَلَا ٱلظِّلُّ وَلَا ٱلْحَرُورُ

Transliteration walā l-ẓilu walā l-ḥarūru

Yoruba Àwọn ibòji àti ìgbóná òòrùn (kò dọ́gba).

Verse 22

وَمَا يَسْتَوِى ٱلْأَحْيَآءُ وَلَا ٱلْأَمْوَٰتُ ۚ إِنَّ ٱللَّهَ يُسْمِعُ مَن يَشَآءُ ۖ وَمَآ أَنتَ بِمُسْمِعٍ مَّن فِى ٱلْقُبُورِ

Transliteration wamā yastawī l-aḥyāu walā l-amwātu inna l-laha yus'miʿu man yashāu wamā anta bimus'miʿin man fī l-qubūri

Yoruba Àwọn alààyè àti òkú kò dọ́gba. Dájúdájú Allāhu l’Ó ń fún ẹni tí Ó bá fẹ́ ní ọ̀rọ̀ gbọ́. Ìwọ kò sì lè fún ẹni tí ó wà nínú sàréè ní ọ̀rọ̀ gbọ́.1

Verse 23

إِنْ أَنتَ إِلَّا نَذِيرٌ

Transliteration in anta illā nadhīrun

Yoruba Ìwọ kò jẹ́ kiní kan bí kò ṣe olùkìlọ̀.

Verse 24

إِنَّآ أَرْسَلْنَـٰكَ بِٱلْحَقِّ بَشِيرًا وَنَذِيرًا ۚ وَإِن مِّنْ أُمَّةٍ إِلَّا خَلَا فِيهَا نَذِيرٌ

Transliteration innā arsalnāka bil-ḥaqi bashīran wanadhīran wa-in min ummatin illā khalā fīhā nadhīrun

Yoruba Dájúdájú Àwa fi òdodo rán ọ níṣẹ́. (O sì jẹ́) oníròó-ìdùnnú àti olùkìlọ̀. Kò sí ìjọ kan (ṣíwájú rẹ) àfi kí olùkìlọ̀ ti rè kọjá láààrin wọn.1

Verse 25

وَإِن يُكَذِّبُوكَ فَقَدْ كَذَّبَ ٱلَّذِينَ مِن قَبْلِهِمْ جَآءَتْهُمْ رُسُلُهُم بِٱلْبَيِّنَـٰتِ وَبِٱلزُّبُرِ وَبِٱلْكِتَـٰبِ ٱلْمُنِيرِ

Transliteration wa-in yukadhibūka faqad kadhaba alladhīna min qablihim jāathum rusuluhum bil-bayināti wabil-zuburi wabil-kitābi l-munīri

Yoruba Tí wọ́n bá sì ń pè ọ́ ní òpùrọ́, àwọn tó ṣíwájú wọn náà kúkú pe (ọ̀rọ̀ Allāhu) ní irọ́ (nígbà tí) àwọn Òjíṣẹ́ wọn wá bá wọn pẹ̀lú àwọn ẹ̀rí tó yanjú, àwọn ìpín-ìpín Tírà àti Tírà tó ń tànmọ́lẹ̀ sí ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn.

Verse 26

ثُمَّ أَخَذْتُ ٱلَّذِينَ كَفَرُوا۟ ۖ فَكَيْفَ كَانَ نَكِيرِ

Transliteration thumma akhadhtu alladhīna kafarū fakayfa kāna nakīri

Yoruba Lẹ́yìn náà, Mo gbá àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ mú. Báwo sì ni bí Mo ṣe (fi ìyà) kọ (aburú fún wọn) ti rí!

Verse 27

أَلَمْ تَرَ أَنَّ ٱللَّهَ أَنزَلَ مِنَ ٱلسَّمَآءِ مَآءً فَأَخْرَجْنَا بِهِۦ ثَمَرَٰتٍ مُّخْتَلِفًا أَلْوَٰنُهَا ۚ وَمِنَ ٱلْجِبَالِ جُدَدٌۢ بِيضٌ وَحُمْرٌ مُّخْتَلِفٌ أَلْوَٰنُهَا وَغَرَابِيبُ سُودٌ

Transliteration alam tara anna l-laha anzala mina l-samāi māan fa-akhrajnā bihi thamarātin mukh'talifan alwānuhā wamina l-jibāli judadun bīḍun waḥum'run mukh'talifun alwānuhā wagharābību sūdun

Yoruba Ṣé o kò rí i pé dájúdájú Allāhu l’Ó sọ omi kalẹ̀ láti sánmọ̀? A sì fi mú àwọn èso tí àwọ̀ rẹ̀ yàtọ̀ síra wọn jáde. Àti pé àwọn ojú ọ̀nà funfun àti pupa tí àwọ̀ rẹ̀ yàtọ̀ síra wọn àti aláwọ̀ dúdú kirikiri wà nínú àwọn àpáta.

Verse 28

وَمِنَ ٱلنَّاسِ وَٱلدَّوَآبِّ وَٱلْأَنْعَـٰمِ مُخْتَلِفٌ أَلْوَٰنُهُۥ كَذَٰلِكَ ۗ إِنَّمَا يَخْشَى ٱللَّهَ مِنْ عِبَادِهِ ٱلْعُلَمَـٰٓؤُا۟ ۗ إِنَّ ٱللَّهَ عَزِيزٌ غَفُورٌ

Transliteration wamina l-nāsi wal-dawābi wal-anʿāmi mukh'talifun alwānuhu kadhālika innamā yakhshā l-laha min ʿibādihi l-ʿulamāu inna l-laha ʿazīzun ghafūrun

Yoruba Àti pé ó wà nínú àwọn ènìyàn, àwọn n̄ǹkan ẹlẹ́mìí àti àwọn ẹran-ọ̀sìn tí àwọ̀ wọn yàtọ̀ síra wọn, gẹ́gẹ́ bí (àwọ̀ èso àti àpáta) wọ̀nyẹn (ṣe yàtọ̀ síra wọn). Àwọn tó ń páyà Allāhu nínú àwọn ẹrúsìn Rẹ̀ ni àwọn onímọ̀ (tí wọ́n mọ̀ pé), dájúdájú Allāhu ni Alágbára, Aláforíjìn.1

Verse 29

إِنَّ ٱلَّذِينَ يَتْلُونَ كِتَـٰبَ ٱللَّهِ وَأَقَامُوا۟ ٱلصَّلَوٰةَ وَأَنفَقُوا۟ مِمَّا رَزَقْنَـٰهُمْ سِرًّا وَعَلَانِيَةً يَرْجُونَ تِجَـٰرَةً لَّن تَبُورَ

Transliteration inna alladhīna yatlūna kitāba l-lahi wa-aqāmū l-ṣalata wa-anfaqū mimmā razaqnāhum sirran waʿalāniyatan yarjūna tijāratan lan tabūra

Yoruba Dájúdájú àwọn tó ń ké tírà Allāhu, tí wọ́n ń kírun, tí wọ́n sì ń ná nínú n̄ǹkan tí A ṣe ní arísìkí fún wọn ní ìkọ̀kọ̀ àti ní gban̄gba, wọ́n ń nírètí sí òwò kan tí kò níí parun.

Verse 30

لِيُوَفِّيَهُمْ أُجُورَهُمْ وَيَزِيدَهُم مِّن فَضْلِهِۦٓ ۚ إِنَّهُۥ غَفُورٌ شَكُورٌ

Transliteration liyuwaffiyahum ujūrahum wayazīdahum min faḍlihi innahu ghafūrun shakūrun

Yoruba (Wọ́n ń ṣe bẹ́ẹ̀) nítorí kí Allāhu lè san wọ́n ní ẹ̀san rere wọn ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àti nítorí kí Ó lè ṣe àlékún fún wọn nínú oore àjùlọ Rẹ̀. Dájúdájú Òun ni Aláforíjìn, Ọlọ́pẹ́.1

Verse 31

وَٱلَّذِىٓ أَوْحَيْنَآ إِلَيْكَ مِنَ ٱلْكِتَـٰبِ هُوَ ٱلْحَقُّ مُصَدِّقًا لِّمَا بَيْنَ يَدَيْهِ ۗ إِنَّ ٱللَّهَ بِعِبَادِهِۦ لَخَبِيرٌۢ بَصِيرٌ

Transliteration wa-alladhī awḥaynā ilayka mina l-kitābi huwa l-ḥaqu muṣaddiqan limā bayna yadayhi inna l-laha biʿibādihi lakhabīrun baṣīrun

Yoruba Ohun tí A fi ránṣẹ́ sí ọ nínú Tírà, òhun ni òdodo tí ó ń fi ohun tó jẹ́ òdodo rinlẹ̀ nípa èyí tó ṣíwájú rẹ̀. Dájúdájú Allāhu ni Onímọ̀-ìkọ̀kọ̀, Olùríran nípa àwọn ẹrúsìn Rẹ̀.

Verse 32

ثُمَّ أَوْرَثْنَا ٱلْكِتَـٰبَ ٱلَّذِينَ ٱصْطَفَيْنَا مِنْ عِبَادِنَا ۖ فَمِنْهُمْ ظَالِمٌ لِّنَفْسِهِۦ وَمِنْهُم مُّقْتَصِدٌ وَمِنْهُمْ سَابِقٌۢ بِٱلْخَيْرَٰتِ بِإِذْنِ ٱللَّهِ ۚ ذَٰلِكَ هُوَ ٱلْفَضْلُ ٱلْكَبِيرُ

Transliteration thumma awrathnā l-kitāba alladhīna iṣ'ṭafaynā min ʿibādinā famin'hum ẓālimun linafsihi wamin'hum muq'taṣidun wamin'hum sābiqun bil-khayrāti bi-idh'ni l-lahi dhālika huwa l-faḍlu l-kabīru

Yoruba Lẹ́yìn náà, A jogún tírà (al-Ƙur’ān) fún àwọn tí A ṣà lẹ́ṣà nínú àwọn ẹrúsìn Wa. Nítorí náà, alábòsí tó ń bo ẹ̀mí ara rẹ̀ sí wà nínú wọn. Olùṣe-déédé wà nínú wọn. Olùgbawájú níbi àwọn iṣẹ́ rere tún wà nínú wọn pẹ̀lú ìyọ̀ǹda Allāhu. Ìyẹn sì ni oore àjùlọ tó tóbi.1

Verse 33

جَنَّـٰتُ عَدْنٍ يَدْخُلُونَهَا يُحَلَّوْنَ فِيهَا مِنْ أَسَاوِرَ مِن ذَهَبٍ وَلُؤْلُؤًا ۖ وَلِبَاسُهُمْ فِيهَا حَرِيرٌ

Transliteration jannātu ʿadnin yadkhulūnahā yuḥallawna fīhā min asāwira min dhahabin walu'lu-an walibāsuhum fīhā ḥarīrun

Yoruba Àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra gbére ni wọn yóò wọ inú rẹ̀. Àwọn kerewú wúrà àti òkúta olówó iyebíye ni A óò máa fi ṣe ọ̀ṣọ́ fún wọn nínú rẹ̀. Àti pé aṣọ àláárì ni aṣọ wọn nínú rẹ̀.

Verse 34

وَقَالُوا۟ ٱلْحَمْدُ لِلَّهِ ٱلَّذِىٓ أَذْهَبَ عَنَّا ٱلْحَزَنَ ۖ إِنَّ رَبَّنَا لَغَفُورٌ شَكُورٌ

Transliteration waqālū l-ḥamdu lillahi alladhī adhhaba ʿannā l-ḥazana inna rabbanā laghafūrun shakūrun

Yoruba Wọ́n yóò sọ pé: “Gbogbo ẹyìn ń jẹ́ ti Allāhu, Ẹni tí Ó mú ìbànújẹ́ kúrò fún wa. Dájúdájú Olúwa wa ni Aláforíjìn, Ọlọ́pẹ́,1

Verse 35

ٱلَّذِىٓ أَحَلَّنَا دَارَ ٱلْمُقَامَةِ مِن فَضْلِهِۦ لَا يَمَسُّنَا فِيهَا نَصَبٌ وَلَا يَمَسُّنَا فِيهَا لُغُوبٌ

Transliteration alladhī aḥallanā dāra l-muqāmati min faḍlihi lā yamassunā fīhā naṣabun walā yamassunā fīhā lughūbun

Yoruba Ẹni tí Ó sọ̀ wá kalẹ̀ sínú ibùgbé gbére nínú oore àjùlọ Rẹ̀. Wàhálà kan kò níí kàn wá nínú rẹ̀. Ìkáàárẹ̀ kan kò sì níí bá wa nínú rẹ̀.

Verse 36

وَٱلَّذِينَ كَفَرُوا۟ لَهُمْ نَارُ جَهَنَّمَ لَا يُقْضَىٰ عَلَيْهِمْ فَيَمُوتُوا۟ وَلَا يُخَفَّفُ عَنْهُم مِّنْ عَذَابِهَا ۚ كَذَٰلِكَ نَجْزِى كُلَّ كَفُورٍ

Transliteration wa-alladhīna kafarū lahum nāru jahannama lā yuq'ḍā ʿalayhim fayamūtū walā yukhaffafu ʿanhum min ʿadhābihā kadhālika najzī kulla kafūrin

Yoruba Àti pé àwọn tó ṣàì gbàgbọ́, iná Jahanamọ ń bẹ fún wọn. A ò níí pa wọ́n (sínú rẹ̀), áḿbọ̀sìbọ́sí pé wọ́n yóò kú. A ò níí ṣe ìyà inú rẹ̀ ní fífúyẹ́ fún wọn. Báyẹn ni A ṣe ń san gbogbo àwọn aláìgbàgbọ́ ní ẹ̀san.

Verse 37

وَهُمْ يَصْطَرِخُونَ فِيهَا رَبَّنَآ أَخْرِجْنَا نَعْمَلْ صَـٰلِحًا غَيْرَ ٱلَّذِى كُنَّا نَعْمَلُ ۚ أَوَلَمْ نُعَمِّرْكُم مَّا يَتَذَكَّرُ فِيهِ مَن تَذَكَّرَ وَجَآءَكُمُ ٱلنَّذِيرُ ۖ فَذُوقُوا۟ فَمَا لِلظَّـٰلِمِينَ مِن نَّصِيرٍ

Transliteration wahum yaṣṭarikhūna fīhā rabbanā akhrij'nā naʿmal ṣāliḥan ghayra alladhī kunnā naʿmalu awalam nuʿammir'kum mā yatadhakkaru fīhi man tadhakkara wajāakumu l-nadhīru fadhūqū famā lilẓẓālimīna min naṣīrin

Yoruba Wọn yóò máa lọgun ìrànlọ́wọ́ nínú rẹ̀ pé: “Olúwa wa, mú wa jáde nítorí kí á lè lọ́ ṣe iṣẹ́ rere, yàtọ̀ sí èyí tí a máa ń ṣe.” Ṣé A ò fún yín ní ẹ̀mí gígùn lò tó fún ẹni tí ọ́ bá fẹ́ lo ìṣítí láti rí i lò nínú àsìkò náà ni? Olùkìlọ̀ sì wá ba yín. Nítorí náà, ẹ tọ́ ìyà wò. Kò sì níí sí alárànṣe kan fún àwọn alábòsí.

Verse 38

إِنَّ ٱللَّهَ عَـٰلِمُ غَيْبِ ٱلسَّمَـٰوَٰتِ وَٱلْأَرْضِ ۚ إِنَّهُۥ عَلِيمٌۢ بِذَاتِ ٱلصُّدُورِ

Transliteration inna l-laha ʿālimu ghaybi l-samāwāti wal-arḍi innahu ʿalīmun bidhāti l-ṣudūri

Yoruba Dájúdájú Allāhu ni Onímọ̀-ìkọ̀kọ̀ àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Dájúdájú Òun ni Onímọ̀ nípa ohun tó wà nínú igbá-àyà ẹ̀dá.

Verse 39

هُوَ ٱلَّذِى جَعَلَكُمْ خَلَـٰٓئِفَ فِى ٱلْأَرْضِ ۚ فَمَن كَفَرَ فَعَلَيْهِ كُفْرُهُۥ ۖ وَلَا يَزِيدُ ٱلْكَـٰفِرِينَ كُفْرُهُمْ عِندَ رَبِّهِمْ إِلَّا مَقْتًا ۖ وَلَا يَزِيدُ ٱلْكَـٰفِرِينَ كُفْرُهُمْ إِلَّا خَسَارًا

Transliteration huwa alladhī jaʿalakum khalāifa fī l-arḍi faman kafara faʿalayhi kuf'ruhu walā yazīdu l-kāfirīna kuf'ruhum ʿinda rabbihim illā maqtan walā yazīdu l-kāfirīna kuf'ruhum illā khasāran

Yoruba Òun ní Ẹni tó ń fi yín ṣe àrólé lórí ilẹ̀. Nítorí náà, ẹni tí ó bá ṣàì gbàgbọ́, (ìyà) àìgbàgbọ́ rẹ̀ wà lórí rẹ̀. Àìgbàgbọ́ àwọn aláìgbàgbọ́ kò sì níí fún wọn ní àlékún kan lọ́dọ̀ Olúwa wọn bí kò ṣe ìbínú. Àìgbàgbọ́ àwọn aláìgbàgbọ́ kò sì níí fún wọn ní àlékún kan bí kò ṣe òfò.

Verse 40

قُلْ أَرَءَيْتُمْ شُرَكَآءَكُمُ ٱلَّذِينَ تَدْعُونَ مِن دُونِ ٱللَّهِ أَرُونِى مَاذَا خَلَقُوا۟ مِنَ ٱلْأَرْضِ أَمْ لَهُمْ شِرْكٌ فِى ٱلسَّمَـٰوَٰتِ أَمْ ءَاتَيْنَـٰهُمْ كِتَـٰبًا فَهُمْ عَلَىٰ بَيِّنَتٍ مِّنْهُ ۚ بَلْ إِن يَعِدُ ٱلظَّـٰلِمُونَ بَعْضُهُم بَعْضًا إِلَّا غُرُورًا

Transliteration qul ara-aytum shurakāakumu alladhīna tadʿūna min dūni l-lahi arūnī mādhā khalaqū mina l-arḍi am lahum shir'kun fī l-samāwāti am ātaynāhum kitāban fahum ʿalā bayyinatin min'hu bal in yaʿidu l-ẓālimūna baʿḍuhum baʿḍan illā ghurūran

Yoruba Sọ pé: “Ẹ sọ fún mi nípa àwọn òrìṣà yín tí ẹ̀ ń pè lẹ́yìn Allāhu, ẹ fi ohun tí wọ́n dá hàn mí lórí ilẹ̀? Tàbí wọ́n ní ìpín kan (pẹ̀lú Allāhu) níbi (ìṣẹ̀dá) àwọn sánmọ̀? Tàbí A fún wọn ní tírà kan, tí wọ́n ní ẹ̀rí tó yanjú lọ́wọ́ nínú rẹ̀? Rárá o! Kò sí àdéhùn kan tí àwọn alábòsí, apá kan wọn ń ṣe fún apá kan bí kò ṣe ẹ̀tàn.”

Verse 41

۞ إِنَّ ٱللَّهَ يُمْسِكُ ٱلسَّمَـٰوَٰتِ وَٱلْأَرْضَ أَن تَزُولَا ۚ وَلَئِن زَالَتَآ إِنْ أَمْسَكَهُمَا مِنْ أَحَدٍ مِّنۢ بَعْدِهِۦٓ ۚ إِنَّهُۥ كَانَ حَلِيمًا غَفُورًا

Transliteration inna l-laha yum'siku l-samāwāti wal-arḍa an tazūlā wala-in zālatā in amsakahumā min aḥadin min baʿdihi innahu kāna ḥalīman ghafūran

Yoruba Dájúdájú Allāhu l’Ó ń mú àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ dúró ṣinṣin tí wọn kò fi yẹ̀ lulẹ̀. Dájúdájú tí wọ́n bá sì yẹ̀ lulẹ̀, kò sí ẹnì kan kan tí ó máa mú un dúró lẹ́yìn Rẹ̀. Dájúdájú Allāhu ń jẹ́ Aláfaradà, Aláforíjìn.

Verse 42

وَأَقْسَمُوا۟ بِٱللَّهِ جَهْدَ أَيْمَـٰنِهِمْ لَئِن جَآءَهُمْ نَذِيرٌ لَّيَكُونُنَّ أَهْدَىٰ مِنْ إِحْدَى ٱلْأُمَمِ ۖ فَلَمَّا جَآءَهُمْ نَذِيرٌ مَّا زَادَهُمْ إِلَّا نُفُورًا

Transliteration wa-aqsamū bil-lahi jahda aymānihim la-in jāahum nadhīrun layakūnunna ahdā min iḥ'dā l-umami falammā jāahum nadhīrun mā zādahum illā nufūran

Yoruba Wọ́n sì fi Allāhu búra tí ìbúra wọn sì lágbára gan-an pé: “Dájúdájú tí olùkìlọ̀ kan bá fi lè wá bá àwọn, dájúdájú àwọn yóò mọ̀nà tààrà ju èyíkéyìí nínú ìjọ (tó ti ṣíwájú).” Nígbà tí olùkìlọ̀ kan sì wá bá wọn, (èyí) kò ṣe àlékún kan fún wọn bí kò ṣe sísá (fún òdodo)

Verse 43

ٱسْتِكْبَارًا فِى ٱلْأَرْضِ وَمَكْرَ ٱلسَّيِّئِ ۚ وَلَا يَحِيقُ ٱلْمَكْرُ ٱلسَّيِّئُ إِلَّا بِأَهْلِهِۦ ۚ فَهَلْ يَنظُرُونَ إِلَّا سُنَّتَ ٱلْأَوَّلِينَ ۚ فَلَن تَجِدَ لِسُنَّتِ ٱللَّهِ تَبْدِيلًا ۖ وَلَن تَجِدَ لِسُنَّتِ ٱللَّهِ تَحْوِيلًا

Transliteration is'tik'bāran fī l-arḍi wamakra l-sayi-i walā yaḥīqu l-makru l-sayi-u illā bi-ahlihi fahal yanẓurūna illā sunnata l-awalīna falan tajida lisunnati l-lahi tabdīlan walan tajida lisunnati l-lahi taḥwīlan

Yoruba ní ti ṣíṣe ìgbéraga lórí ilẹ̀ àti ní ti ète aburú. Ète aburú kò sì níí yí ẹnì kan po àfi oníṣẹ́ aburú. Ṣé wọ́n ń retí kiní kan bí kò ṣe ìṣe(Allāhu lórí) àwọn ẹni àkọ́kọ́?Nítorí náà, o ò níí rí ìpààrọ̀ fún ìṣe Allāhu. Àní sẹ́, o ò níí rí ìyípadà fún ìṣe Allāhu.

Verse 44

أَوَلَمْ يَسِيرُوا۟ فِى ٱلْأَرْضِ فَيَنظُرُوا۟ كَيْفَ كَانَ عَـٰقِبَةُ ٱلَّذِينَ مِن قَبْلِهِمْ وَكَانُوٓا۟ أَشَدَّ مِنْهُمْ قُوَّةً ۚ وَمَا كَانَ ٱللَّهُ لِيُعْجِزَهُۥ مِن شَىْءٍ فِى ٱلسَّمَـٰوَٰتِ وَلَا فِى ٱلْأَرْضِ ۚ إِنَّهُۥ كَانَ عَلِيمًا قَدِيرًا

Transliteration awalam yasīrū fī l-arḍi fayanẓurū kayfa kāna ʿāqibatu alladhīna min qablihim wakānū ashadda min'hum quwwatan wamā kāna l-lahu liyuʿ'jizahu min shayin fī l-samāwāti walā fī l-arḍi innahu kāna ʿalīman qadīran

Yoruba Ṣé wọn kò rìn kiri lórí ilẹ̀ kí wọ́n wo bí ìkángun àwọn tó ṣíwájú wọn ṣe rí? Wọ́n sì ní agbára ju àwọn (wọ̀nyí) lọ! Àti pé kò sí kiní kan nínú àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ tí ó lè mórí bọ́ lọ́wọ́ Allāhu. Dájúdájú Allāhu ń jẹ́ Onímọ̀, Alágbára.

Verse 45

وَلَوْ يُؤَاخِذُ ٱللَّهُ ٱلنَّاسَ بِمَا كَسَبُوا۟ مَا تَرَكَ عَلَىٰ ظَهْرِهَا مِن دَآبَّةٍ وَلَـٰكِن يُؤَخِّرُهُمْ إِلَىٰٓ أَجَلٍ مُّسَمًّى ۖ فَإِذَا جَآءَ أَجَلُهُمْ فَإِنَّ ٱللَّهَ كَانَ بِعِبَادِهِۦ بَصِيرًۢا

Transliteration walaw yuākhidhu l-lahu l-nāsa bimā kasabū mā taraka ʿalā ẓahrihā min dābbatin walākin yu-akhiruhum ilā ajalin musamman fa-idhā jāa ajaluhum fa-inna l-laha kāna biʿibādihi baṣīran

Yoruba Tí ó bá jẹ́ pé Allāhu yó (tètè) máa mú ènìyàn pẹ̀lú ohun tí wọ́n ṣe níṣẹ́ ni, ìbá tí ṣẹ́ ku n̄ǹkan ẹlẹ́mìí kan kan mọ́ lórí ilẹ̀. Ṣùgbọ́n Ó ń lọ́ wọn lára di gbèdéke àkókò kan. Nígbà tí àkókò náà bá dé, dájúdájú Allāhu ni Olùríran nípa àwọn ẹrúsìn Rẹ̀.

Read Surah Fatir in another language

All languages

All 114 surahs in Yoruba: the Qur’an in Yoruba.

Learn it in MyDugsi

Yoruba translation: Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni, from Quran.com. Transliteration: Quran.com. Recitation: Mishary Alafasy, from EveryAyah.com. MyDugsi is a learning aid, not a replacement for a qualified teacher.