Surah At-Tawbah in Yoruba: translation and audio
Surah 9 · التوبة · The Repentance · 129 verses
Surah At-Tawbah verse by verse: the Arabic with a recitation you can repeat, the transliteration, and the Yoruba translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni. For the meaning of every word, see Surah At-Tawbah word by word in English.
Verse 1
بَرَآءَةٌ مِّنَ ٱللَّهِ وَرَسُولِهِۦٓ إِلَى ٱلَّذِينَ عَـٰهَدتُّم مِّنَ ٱلْمُشْرِكِينَ
Transliteration barāatun mina l-lahi warasūlihi ilā alladhīna ʿāhadttum mina l-mush'rikīna
Yoruba (Èyí ni) ìyọwọ́-yọsẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀ sí àwọn tí ẹ ṣe àdéhùn fún nínú àwọn ọ̀ṣẹbọ.
Verse 2
فَسِيحُوا۟ فِى ٱلْأَرْضِ أَرْبَعَةَ أَشْهُرٍ وَٱعْلَمُوٓا۟ أَنَّكُمْ غَيْرُ مُعْجِزِى ٱللَّهِ ۙ وَأَنَّ ٱللَّهَ مُخْزِى ٱلْكَـٰفِرِينَ
Transliteration fasīḥū fī l-arḍi arbaʿata ashhurin wa-iʿ'lamū annakum ghayru muʿ'jizī l-lahi wa-anna l-laha mukh'zī l-kāfirīna
Yoruba Nítorí náà, (ẹ̀yin ọ̀ṣẹbọ) ẹ rìn (kiri) lórí ilẹ̀ fún oṣù mẹ́rin. Kí ẹ sì mọ̀ pé dájúdájú ẹ̀yin kò lè mórí bọ́ (nínú ìyà) Allāhu. Àti pé dájúdájú Allāhu yóò dójú ti àwọn aláìgbàgbọ́.
Verse 3
وَأَذَٰنٌ مِّنَ ٱللَّهِ وَرَسُولِهِۦٓ إِلَى ٱلنَّاسِ يَوْمَ ٱلْحَجِّ ٱلْأَكْبَرِ أَنَّ ٱللَّهَ بَرِىٓءٌ مِّنَ ٱلْمُشْرِكِينَ ۙ وَرَسُولُهُۥ ۚ فَإِن تُبْتُمْ فَهُوَ خَيْرٌ لَّكُمْ ۖ وَإِن تَوَلَّيْتُمْ فَٱعْلَمُوٓا۟ أَنَّكُمْ غَيْرُ مُعْجِزِى ٱللَّهِ ۗ وَبَشِّرِ ٱلَّذِينَ كَفَرُوا۟ بِعَذَابٍ أَلِيمٍ
Transliteration wa-adhānun mina l-lahi warasūlihi ilā l-nāsi yawma l-ḥaji l-akbari anna l-laha barīon mina l-mush'rikīna warasūluhu fa-in tub'tum fahuwa khayrun lakum wa-in tawallaytum fa-iʿ'lamū annakum ghayru muʿ'jizī l-lahi wabashiri alladhīna kafarū biʿadhābin alīmin
Yoruba Ìkéde kan láti ọ̀dọ̀ Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀ sí àwọn ènìyàn ní ọjọ́ Hajj Ńláni pé, “Dájúdájú Allāhu yọwọ́yọsẹ̀ (nínú ọ̀rọ̀) àwọn ọ̀ṣẹbọ. Òjíṣẹ́ Rẹ̀ náà (yọwọ́yọsẹ̀). Tí ẹ bá ronú pìwàdà, ó sì lóore jùlọ fún yín. Tí ẹ bá gbúnrí, ẹ mọ̀ pé dájúdájú ẹ kò lè móríbọ́ nínú (ìyà) Allāhu.” Kí o sì fún àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ ní ìró ìyà ẹlẹ́ta-eléro.
Verse 4
إِلَّا ٱلَّذِينَ عَـٰهَدتُّم مِّنَ ٱلْمُشْرِكِينَ ثُمَّ لَمْ يَنقُصُوكُمْ شَيْـًٔا وَلَمْ يُظَـٰهِرُوا۟ عَلَيْكُمْ أَحَدًا فَأَتِمُّوٓا۟ إِلَيْهِمْ عَهْدَهُمْ إِلَىٰ مُدَّتِهِمْ ۚ إِنَّ ٱللَّهَ يُحِبُّ ٱلْمُتَّقِينَ
Transliteration illā alladhīna ʿāhadttum mina l-mush'rikīna thumma lam yanquṣūkum shayan walam yuẓāhirū ʿalaykum aḥadan fa-atimmū ilayhim ʿahdahum ilā muddatihim inna l-laha yuḥibbu l-mutaqīna
Yoruba Àyàfi àwọn tí ẹ bá ṣe àdéhùn nínú àwọn ọ̀ṣẹbọ, lẹ́yìn náà, tí wọn kò sì fi ọ̀nà kan kan yẹ àdéhùn yín, tí wọn kò sì ṣàtìlẹ́yìn fún ẹnì kan kan le yín lórí. Nítorí náà, ẹ pé àdéhùn wọn fún wọn títí di àsìkò wọn. Dájúdájú Allāhu nífẹ̀ẹ́ àwọn olùbẹ̀rù (Rẹ̀).
Verse 5
فَإِذَا ٱنسَلَخَ ٱلْأَشْهُرُ ٱلْحُرُمُ فَٱقْتُلُوا۟ ٱلْمُشْرِكِينَ حَيْثُ وَجَدتُّمُوهُمْ وَخُذُوهُمْ وَٱحْصُرُوهُمْ وَٱقْعُدُوا۟ لَهُمْ كُلَّ مَرْصَدٍ ۚ فَإِن تَابُوا۟ وَأَقَامُوا۟ ٱلصَّلَوٰةَ وَءَاتَوُا۟ ٱلزَّكَوٰةَ فَخَلُّوا۟ سَبِيلَهُمْ ۚ إِنَّ ٱللَّهَ غَفُورٌ رَّحِيمٌ
Transliteration fa-idhā insalakha l-ashhuru l-ḥurumu fa-uq'tulū l-mush'rikīna ḥaythu wajadttumūhum wakhudhūhum wa-uḥ'ṣurūhum wa-uq'ʿudū lahum kulla marṣadin fa-in tābū wa-aqāmū l-ṣalata waātawū l-zakata fakhallū sabīlahum inna l-laha ghafūrun raḥīmun
Yoruba Nítorí náà, nígbà tí àwọn oṣù ọ̀wọ̀ bá lọ tán ẹ pa àwọn ọ̀ṣẹbọ níbikíbi tí ẹ bá ti bá wọn. Ẹ mú wọn, ẹ ṣéde mọ́ wọn, kí ẹ sì ba dè wọ́n ní gbogbo ibùba. Tí wọ́n bá sì ronú pìwàdà, tí wọ́n ń kírun, tí wọ́n sì ń yọ Zakāh, ẹ yàgò fún wọn lójú ọ̀nà. Dájúdájú Allāhu ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.
Verse 6
وَإِنْ أَحَدٌ مِّنَ ٱلْمُشْرِكِينَ ٱسْتَجَارَكَ فَأَجِرْهُ حَتَّىٰ يَسْمَعَ كَلَـٰمَ ٱللَّهِ ثُمَّ أَبْلِغْهُ مَأْمَنَهُۥ ۚ ذَٰلِكَ بِأَنَّهُمْ قَوْمٌ لَّا يَعْلَمُونَ
Transliteration wa-in aḥadun mina l-mush'rikīna is'tajāraka fa-ajir'hu ḥattā yasmaʿa kalāma l-lahi thumma abligh'hu mamanahu dhālika bi-annahum qawmun lā yaʿlamūna
Yoruba Tí ẹnì kan nínú àwọn ọ̀sẹbọ bá wá ètò ààbò wá sọ́dọ̀ rẹ, ṣ’ètò ààbò fún un títí ó fi máa gbọ́ ọ̀rọ̀ Allāhu. Lẹ́yìn náà, mú un dé àyè ìfọ̀kànbalẹ̀ rẹ̀. Ìyẹn nítorí pé dájúdájú àwọn ni ìjọ tí kò nímọ̀.
Verse 7
كَيْفَ يَكُونُ لِلْمُشْرِكِينَ عَهْدٌ عِندَ ٱللَّهِ وَعِندَ رَسُولِهِۦٓ إِلَّا ٱلَّذِينَ عَـٰهَدتُّمْ عِندَ ٱلْمَسْجِدِ ٱلْحَرَامِ ۖ فَمَا ٱسْتَقَـٰمُوا۟ لَكُمْ فَٱسْتَقِيمُوا۟ لَهُمْ ۚ إِنَّ ٱللَّهَ يُحِبُّ ٱلْمُتَّقِينَ
Transliteration kayfa yakūnu lil'mush'rikīna ʿahdun ʿinda l-lahi waʿinda rasūlihi illā alladhīna ʿāhadttum ʿinda l-masjidi l-ḥarāmi famā is'taqāmū lakum fa-is'taqīmū lahum inna l-laha yuḥibbu l-mutaqīna
Yoruba Báwo ni àdéhùn kan yóò ṣe wà fún àwọn ọ̀ṣẹbọ lọ́dọ̀ Allāhu àti lọ́dọ̀ Òjísẹ́ Rẹ̀ yàtọ̀ sí àwọn tí ẹ bá ṣe àdéhùn nítòsí Mọ́sálásí Haram? Nítorí náà, tí wọ́n bá dúró déédé pẹ̀lú yín, ẹ dúró déédé pẹ̀lú wọn. Dájúdájú Allāhu nífẹ̀ẹ́ àwọn olùbẹ̀rù (Rẹ̀).
Verse 8
كَيْفَ وَإِن يَظْهَرُوا۟ عَلَيْكُمْ لَا يَرْقُبُوا۟ فِيكُمْ إِلًّا وَلَا ذِمَّةً ۚ يُرْضُونَكُم بِأَفْوَٰهِهِمْ وَتَأْبَىٰ قُلُوبُهُمْ وَأَكْثَرُهُمْ فَـٰسِقُونَ
Transliteration kayfa wa-in yaẓharū ʿalaykum lā yarqubū fīkum illan walā dhimmatan yur'ḍūnakum bi-afwāhihim watabā qulūbuhum wa-aktharuhum fāsiqūna
Yoruba Báwo (ni àdéhùn kan yóò ṣe wà fún wọn) nígbà tí ó jẹ́ pé tí wọ́n bá borí yín, wọn kò níí ṣọ́ okùn ìbí àti àdéhùn. Wọ́n ń fi ẹnu wọn wí pé àwọn yọ́nú si yín, ọkàn wọn sì kọ̀ ọ́. Ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn sì ni òbìlẹ̀jẹ́.
Verse 9
ٱشْتَرَوْا۟ بِـَٔايَـٰتِ ٱللَّهِ ثَمَنًا قَلِيلًا فَصَدُّوا۟ عَن سَبِيلِهِۦٓ ۚ إِنَّهُمْ سَآءَ مَا كَانُوا۟ يَعْمَلُونَ
Transliteration ish'taraw biāyāti l-lahi thamanan qalīlan faṣaddū ʿan sabīlihi innahum sāa mā kānū yaʿmalūna
Yoruba Wọ́n ta àwọn āyah Allāhu ní owó pọ́ọ́kú, wọ́n sì ṣẹ́rí àwọn ènìyàn kúrò lójú ọ̀nà (ẹ̀sìn) Rẹ̀. Dájúdájú àwọn (wọ̀nyí), ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́ burú.
Verse 10
لَا يَرْقُبُونَ فِى مُؤْمِنٍ إِلًّا وَلَا ذِمَّةً ۚ وَأُو۟لَـٰٓئِكَ هُمُ ٱلْمُعْتَدُونَ
Transliteration lā yarqubūna fī mu'minin illan walā dhimmatan wa-ulāika humu l-muʿ'tadūna
Yoruba Àwọn ọ̀ṣẹbọ kò níí ṣọ́ okùn ìbí àti àdéhùn kan fún onígbàgbọ́ òdodo kan. Àwọn wọ̀nyẹn, àwọn sì ni olùtayọ ẹnu-ààlà.
Verse 11
فَإِن تَابُوا۟ وَأَقَامُوا۟ ٱلصَّلَوٰةَ وَءَاتَوُا۟ ٱلزَّكَوٰةَ فَإِخْوَٰنُكُمْ فِى ٱلدِّينِ ۗ وَنُفَصِّلُ ٱلْـَٔايَـٰتِ لِقَوْمٍ يَعْلَمُونَ
Transliteration fa-in tābū wa-aqāmū l-ṣalata waātawū l-zakata fa-ikh'wānukum fī l-dīni wanufaṣṣilu l-āyāti liqawmin yaʿlamūna
Yoruba Nítorí náà, tí wọ́n bá ronú pìwàdà, tí wọ́n ń kírun, tí wọ́n sì ń yọ Zakāh, nígbà náà ọmọ-ìyá yín nínú ẹ̀sìn ni wọ́n. À ń ṣàlàyé àwọn āyah náà fún ìjọ tó nímọ̀.
Verse 12
وَإِن نَّكَثُوٓا۟ أَيْمَـٰنَهُم مِّنۢ بَعْدِ عَهْدِهِمْ وَطَعَنُوا۟ فِى دِينِكُمْ فَقَـٰتِلُوٓا۟ أَئِمَّةَ ٱلْكُفْرِ ۙ إِنَّهُمْ لَآ أَيْمَـٰنَ لَهُمْ لَعَلَّهُمْ يَنتَهُونَ
Transliteration wa-in nakathū aymānahum min baʿdi ʿahdihim waṭaʿanū fī dīnikum faqātilū a-immata l-kuf'ri innahum lā aymāna lahum laʿallahum yantahūna
Yoruba Tí wọ́n bá rú ìbúra wọn lẹ́yìn àdéhùn wọn, tí wọ́n sì ń sọ̀rọ̀ àìdara sí ẹ̀sìn yín, nígbà náà ẹ ja àwọn olórí aláìgbàgbọ́ lógun - dájúdájú ìbúra wọn kò ní ìtúmọ̀ kan sí wọn - kí wọ́n lè jáwọ́ (níbi aburú).
Verse 13
أَلَا تُقَـٰتِلُونَ قَوْمًا نَّكَثُوٓا۟ أَيْمَـٰنَهُمْ وَهَمُّوا۟ بِإِخْرَاجِ ٱلرَّسُولِ وَهُم بَدَءُوكُمْ أَوَّلَ مَرَّةٍ ۚ أَتَخْشَوْنَهُمْ ۚ فَٱللَّهُ أَحَقُّ أَن تَخْشَوْهُ إِن كُنتُم مُّؤْمِنِينَ
Transliteration alā tuqātilūna qawman nakathū aymānahum wahammū bi-ikh'rāji l-rasūli wahum badaūkum awwala marratin atakhshawnahum fal-lahu aḥaqqu an takhshawhu in kuntum mu'minīna
Yoruba Ṣé ẹ ò níí gbógun ti ìjọ kan tó ba ìbúra rẹ̀ jẹ́ (ó sì jù ú nù), tí wọ́n sì gbèrò láti lé Òjíṣẹ́ kúrò (nínú ìlú); àwọn sì ni wọ́n kọ́ bẹ̀rẹ̀ sí gbógun tì yín ní ìgbà àkọ́kọ́? Ṣé ẹ̀ ń páyà wọn ni? Allāhu l’Ó ní ẹ̀tọ́ jùlọ sí pé kí ẹ páyà Rẹ̀ tí ẹ bá jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo.1
Verse 14
قَـٰتِلُوهُمْ يُعَذِّبْهُمُ ٱللَّهُ بِأَيْدِيكُمْ وَيُخْزِهِمْ وَيَنصُرْكُمْ عَلَيْهِمْ وَيَشْفِ صُدُورَ قَوْمٍ مُّؤْمِنِينَ
Transliteration qātilūhum yuʿadhib'humu l-lahu bi-aydīkum wayukh'zihim wayanṣur'kum ʿalayhim wayashfi ṣudūra qawmin mu'minīna
Yoruba Ẹ jà wọ́n lógun. Allāhu yóò jẹ wọ́n níyà láti ọwọ́ yín. Ó máa yẹpẹrẹ wọn. Ó máa ràn yín lọ́wọ́ lórí wọn. Ó sì máa wo ọkàn ìjọ onígbàgbọ́ òdodo sàn.
Verse 15
وَيُذْهِبْ غَيْظَ قُلُوبِهِمْ ۗ وَيَتُوبُ ٱللَّهُ عَلَىٰ مَن يَشَآءُ ۗ وَٱللَّهُ عَلِيمٌ حَكِيمٌ
Transliteration wayudh'hib ghayẓa qulūbihim wayatūbu l-lahu ʿalā man yashāu wal-lahu ʿalīmun ḥakīmun
Yoruba Ó tún máa kó ìbínú ọkàn wọn lọ. Ó sì máa gba ìronúpìwàdà lọ́wọ́ ẹni t’Ó bá fẹ́. Allāhu sì ni Onímọ̀, Ọlọ́gbọ́n.
Verse 16
أَمْ حَسِبْتُمْ أَن تُتْرَكُوا۟ وَلَمَّا يَعْلَمِ ٱللَّهُ ٱلَّذِينَ جَـٰهَدُوا۟ مِنكُمْ وَلَمْ يَتَّخِذُوا۟ مِن دُونِ ٱللَّهِ وَلَا رَسُولِهِۦ وَلَا ٱلْمُؤْمِنِينَ وَلِيجَةً ۚ وَٱللَّهُ خَبِيرٌۢ بِمَا تَعْمَلُونَ
Transliteration am ḥasib'tum an tut'rakū walammā yaʿlami l-lahu alladhīna jāhadū minkum walam yattakhidhū min dūni l-lahi walā rasūlihi walā l-mu'minīna walījatan wal-lahu khabīrun bimā taʿmalūna
Yoruba Tàbí ẹ lérò pé A óò fi yín sílẹ̀ láì jẹ́ pé Allāhu ti ṣàfi hàn àwọn tó máa jagun ẹ̀sìn nínú yín, tí wọn kò sì ní ọ̀rẹ́ àyò kan lẹ́yìn Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀ àti àwọn onígbàgbọ́ òdodo? Allāhu ni Alámọ̀tán nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.
Verse 17
مَا كَانَ لِلْمُشْرِكِينَ أَن يَعْمُرُوا۟ مَسَـٰجِدَ ٱللَّهِ شَـٰهِدِينَ عَلَىٰٓ أَنفُسِهِم بِٱلْكُفْرِ ۚ أُو۟لَـٰٓئِكَ حَبِطَتْ أَعْمَـٰلُهُمْ وَفِى ٱلنَّارِ هُمْ خَـٰلِدُونَ
Transliteration mā kāna lil'mush'rikīna an yaʿmurū masājida l-lahi shāhidīna ʿalā anfusihim bil-kuf'ri ulāika ḥabiṭat aʿmāluhum wafī l-nāri hum khālidūna
Yoruba Kò lẹ́tọ̀ọ́ fún àwọn ọ̀ṣẹbọ láti máa ṣàmójútó àwọn mọ́sálásí Allāhu, nígbà tí wọ́n jẹ́ ẹlẹ́rìí sí àìgbàgbọ́ lórí ara wọn. Àwọn wọ̀nyẹn ni iṣẹ́ wọn ti bàjẹ́. Olùṣegbére sì ni wọ́n nínú Iná.
Verse 18
إِنَّمَا يَعْمُرُ مَسَـٰجِدَ ٱللَّهِ مَنْ ءَامَنَ بِٱللَّهِ وَٱلْيَوْمِ ٱلْـَٔاخِرِ وَأَقَامَ ٱلصَّلَوٰةَ وَءَاتَى ٱلزَّكَوٰةَ وَلَمْ يَخْشَ إِلَّا ٱللَّهَ ۖ فَعَسَىٰٓ أُو۟لَـٰٓئِكَ أَن يَكُونُوا۟ مِنَ ٱلْمُهْتَدِينَ
Transliteration innamā yaʿmuru masājida l-lahi man āmana bil-lahi wal-yawmi l-ākhiri wa-aqāma l-ṣalata waātā l-zakata walam yakhsha illā l-laha faʿasā ulāika an yakūnū mina l-muh'tadīna
Yoruba Ẹni tí yóò máa ṣàmójútó àwọn mọ́sálásí Allāhu ni ẹni tó gbàgbọ́ nínú Allāhu àti Ọjọ́ Ìkẹ́yìn, tó sì ń kírun, tó ń yọ Zakāh, kò sì páyà (òrìṣà kan) lẹ́yìn Allāhu. Àwọn wọ̀nyẹn ni wọ́n kúkú wà nínú àwọn olùmọ̀nà.
Verse 19
۞ أَجَعَلْتُمْ سِقَايَةَ ٱلْحَآجِّ وَعِمَارَةَ ٱلْمَسْجِدِ ٱلْحَرَامِ كَمَنْ ءَامَنَ بِٱللَّهِ وَٱلْيَوْمِ ٱلْـَٔاخِرِ وَجَـٰهَدَ فِى سَبِيلِ ٱللَّهِ ۚ لَا يَسْتَوُۥنَ عِندَ ٱللَّهِ ۗ وَٱللَّهُ لَا يَهْدِى ٱلْقَوْمَ ٱلظَّـٰلِمِينَ
Transliteration ajaʿaltum siqāyata l-ḥāji waʿimārata l-masjidi l-ḥarāmi kaman āmana bil-lahi wal-yawmi l-ākhiri wajāhada fī sabīli l-lahi lā yastawūna ʿinda l-lahi wal-lahu lā yahdī l-qawma l-ẓālimīna
Yoruba Ṣé ẹ máa ṣe fífún alálàájì ní omi mu àti ṣíṣe àmójútó Mọ́sálásí Haram ní ohun tó dọ́gba sí ẹni tó gbàgbọ́ nínú Allāhu àti Ọjọ́ Ìkẹ́yìn, tó sì jagun sójú ọ̀nà (ẹ̀sìn) Allāhu? Wọn kò dọ́gba lọ́dọ̀ Allāhu. Allāhu kò níí fi ọ̀nà mọ ìjọ alábòsí.
Verse 20
ٱلَّذِينَ ءَامَنُوا۟ وَهَاجَرُوا۟ وَجَـٰهَدُوا۟ فِى سَبِيلِ ٱللَّهِ بِأَمْوَٰلِهِمْ وَأَنفُسِهِمْ أَعْظَمُ دَرَجَةً عِندَ ٱللَّهِ ۚ وَأُو۟لَـٰٓئِكَ هُمُ ٱلْفَآئِزُونَ
Transliteration alladhīna āmanū wahājarū wajāhadū fī sabīli l-lahi bi-amwālihim wa-anfusihim aʿẓamu darajatan ʿinda l-lahi wa-ulāika humu l-fāizūna
Yoruba Àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n gbé ìlú wọn jù sílẹ̀,tí wọ́n sì fi dúkìá wọn àti ẹ̀mí wọn jagun fún ẹ̀sìn Allāhu, wọ́n tóbi jùlọ ní ipò lọ́dọ̀ Allāhu. Àwọn wọ̀nyẹn, àwọn sì ni olùjèrè.
Verse 21
يُبَشِّرُهُمْ رَبُّهُم بِرَحْمَةٍ مِّنْهُ وَرِضْوَٰنٍ وَجَنَّـٰتٍ لَّهُمْ فِيهَا نَعِيمٌ مُّقِيمٌ
Transliteration yubashiruhum rabbuhum biraḥmatin min'hu wariḍ'wānin wajannātin lahum fīhā naʿīmun muqīmun
Yoruba Olúwa wọn ń fún wọn ní ìró ìdùnnú nípa ìkẹ́ láti ọ̀dọ̀ Rẹ̀ pẹ̀lú ìyọ́nú àti àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra kan tí ìdẹ̀ra gbére wà fún wọn nínú rẹ̀.
Verse 22
خَـٰلِدِينَ فِيهَآ أَبَدًا ۚ إِنَّ ٱللَّهَ عِندَهُۥٓ أَجْرٌ عَظِيمٌ
Transliteration khālidīna fīhā abadan inna l-laha ʿindahu ajrun ʿaẓīmun
Yoruba Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀ títí láéláé. Dájúdájú Allāhu, ọ̀dọ̀ Rẹ̀ ni ẹ̀san ńlá wà.
Verse 23
يَـٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُوا۟ لَا تَتَّخِذُوٓا۟ ءَابَآءَكُمْ وَإِخْوَٰنَكُمْ أَوْلِيَآءَ إِنِ ٱسْتَحَبُّوا۟ ٱلْكُفْرَ عَلَى ٱلْإِيمَـٰنِ ۚ وَمَن يَتَوَلَّهُم مِّنكُمْ فَأُو۟لَـٰٓئِكَ هُمُ ٱلظَّـٰلِمُونَ
Transliteration yāayyuhā alladhīna āmanū lā tattakhidhū ābāakum wa-ikh'wānakum awliyāa ini is'taḥabbū l-kuf'ra ʿalā l-īmāni waman yatawallahum minkum fa-ulāika humu l-ẓālimūna
Yoruba Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ má ṣe mú àwọn bàbá yín àti àwọn arakùnrin yín ní ọ̀rẹ́ àyò bí wọ́n bá gbọ́lá fún àìgbàgbọ́ lórí ìgbàgbọ́ òdodo. Ẹnikẹ́ni tó bá mú wọn ní ọ̀rẹ́ àyò nínú yín, àwọn wọ̀nyẹn gan-an ni alábòsí.1
Verse 24
قُلْ إِن كَانَ ءَابَآؤُكُمْ وَأَبْنَآؤُكُمْ وَإِخْوَٰنُكُمْ وَأَزْوَٰجُكُمْ وَعَشِيرَتُكُمْ وَأَمْوَٰلٌ ٱقْتَرَفْتُمُوهَا وَتِجَـٰرَةٌ تَخْشَوْنَ كَسَادَهَا وَمَسَـٰكِنُ تَرْضَوْنَهَآ أَحَبَّ إِلَيْكُم مِّنَ ٱللَّهِ وَرَسُولِهِۦ وَجِهَادٍ فِى سَبِيلِهِۦ فَتَرَبَّصُوا۟ حَتَّىٰ يَأْتِىَ ٱللَّهُ بِأَمْرِهِۦ ۗ وَٱللَّهُ لَا يَهْدِى ٱلْقَوْمَ ٱلْفَـٰسِقِينَ
Transliteration qul in kāna ābāukum wa-abnāukum wa-ikh'wānukum wa-azwājukum waʿashīratukum wa-amwālun iq'taraftumūhā watijāratun takhshawna kasādahā wamasākinu tarḍawnahā aḥabba ilaykum mina l-lahi warasūlihi wajihādin fī sabīlihi fatarabbaṣū ḥattā yatiya l-lahu bi-amrihi wal-lahu lā yahdī l-qawma l-fāsiqīna
Yoruba Sọ pé: “Tí ó bá jẹ́ pé àwọn bàbá yín, àwọn ọmọkùnrin yín, àwọn arákùnrin yín, àwọn ìyàwó yín àti àwọn ìbátan yín pẹ̀lú àwọn dúkìá kan tí ẹ ti kó jọ àti òkòwò kan tí ẹ̀ ń bẹ̀rù pé kí ó má kùtà àti àwọn ibùgbé tí ẹ yọ́nú sí, (tí ìwọ̀nyí) bá wù yín ju Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀ pẹ̀lú jíja ogun sójú ọ̀nà (ẹ̀sìn) Rẹ̀, ẹ máa retí (ìkángun) nígbà náà títí Allāhu yóò fi mú àṣẹ Rẹ̀ wá. Allāhu kò níí fi ọ̀nà mọ ìjọ òbìlẹ̀jẹ́.
Verse 25
لَقَدْ نَصَرَكُمُ ٱللَّهُ فِى مَوَاطِنَ كَثِيرَةٍ ۙ وَيَوْمَ حُنَيْنٍ ۙ إِذْ أَعْجَبَتْكُمْ كَثْرَتُكُمْ فَلَمْ تُغْنِ عَنكُمْ شَيْـًٔا وَضَاقَتْ عَلَيْكُمُ ٱلْأَرْضُ بِمَا رَحُبَتْ ثُمَّ وَلَّيْتُم مُّدْبِرِينَ
Transliteration laqad naṣarakumu l-lahu fī mawāṭina kathīratin wayawma ḥunaynin idh aʿjabatkum kathratukum falam tugh'ni ʿankum shayan waḍāqat ʿalaykumu l-arḍu bimā raḥubat thumma wallaytum mud'birīna
Yoruba Dájúdájú Allāhu ti ṣe àrànṣe fún yín ní ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ojú ogun àti ní ọjọ́ (ogun) Hunaen, nígbà tí pípọ̀ yín jọ yín lójú, (àmọ́) kò rọ̀ yín lọ́rọ̀ kan kan; ilẹ̀ sì fún mọ yín tòhun ti bí ó ṣe fẹ̀ tó. Lẹ́yìn náà, ẹ pẹ̀yìn dà, ẹ sì ń sá lọ.
Verse 26
ثُمَّ أَنزَلَ ٱللَّهُ سَكِينَتَهُۥ عَلَىٰ رَسُولِهِۦ وَعَلَى ٱلْمُؤْمِنِينَ وَأَنزَلَ جُنُودًا لَّمْ تَرَوْهَا وَعَذَّبَ ٱلَّذِينَ كَفَرُوا۟ ۚ وَذَٰلِكَ جَزَآءُ ٱلْكَـٰفِرِينَ
Transliteration thumma anzala l-lahu sakīnatahu ʿalā rasūlihi waʿalā l-mu'minīna wa-anzala junūdan lam tarawhā waʿadhaba alladhīna kafarū wadhālika jazāu l-kāfirīna
Yoruba Lẹ́yìn náà, Allāhu sọ ìfàyàbalẹ̀ Rẹ̀ kalẹ̀ fún Òjíṣẹ́ Rẹ̀ àti fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo. Ó tún sọ àwọn ọmọ ogun kan kalẹ̀, tí ẹ ò fojú rí wọn. Ó sì jẹ àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ níyà. Ìyẹn sì ni ẹ̀san àwọn aláìgbàgbọ́.
Verse 27
ثُمَّ يَتُوبُ ٱللَّهُ مِنۢ بَعْدِ ذَٰلِكَ عَلَىٰ مَن يَشَآءُ ۗ وَٱللَّهُ غَفُورٌ رَّحِيمٌ
Transliteration thumma yatūbu l-lahu min baʿdi dhālika ʿalā man yashāu wal-lahu ghafūrun raḥīmun
Yoruba Lẹ́yìn náà, Allāhu yóò gba ìronúpìwàdà lọ́wọ́ ẹni t’Ó bá fẹ́ lẹ́yìn ìyẹn. Allāhu sì ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.
Verse 28
يَـٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُوٓا۟ إِنَّمَا ٱلْمُشْرِكُونَ نَجَسٌ فَلَا يَقْرَبُوا۟ ٱلْمَسْجِدَ ٱلْحَرَامَ بَعْدَ عَامِهِمْ هَـٰذَا ۚ وَإِنْ خِفْتُمْ عَيْلَةً فَسَوْفَ يُغْنِيكُمُ ٱللَّهُ مِن فَضْلِهِۦٓ إِن شَآءَ ۚ إِنَّ ٱللَّهَ عَلِيمٌ حَكِيمٌ
Transliteration yāayyuhā alladhīna āmanū innamā l-mush'rikūna najasun falā yaqrabū l-masjida l-ḥarāma baʿda ʿāmihim hādhā wa-in khif'tum ʿaylatan fasawfa yugh'nīkumu l-lahu min faḍlihi in shāa inna l-laha ʿalīmun ḥakīmun
Yoruba Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, dájúdájú ẹ̀gbin ni àwọn ọ̀sẹbọ. Nítorí náà, wọn kò gbọdọ̀ súnmọ́ Mọ́sálásí Haram lẹ́yìn ọdún wọn yìí. Tí ẹ bá ń bẹ̀rù òṣì, láìpẹ́ Allāhu máa rọ̀ yín lọ́rọ̀ nínú ọlá Rẹ̀, tí Ó bá fẹ́. Dájúdájú Allāhu ni Onímọ̀, Ọlọ́gbọ́n.
Verse 29
قَـٰتِلُوا۟ ٱلَّذِينَ لَا يُؤْمِنُونَ بِٱللَّهِ وَلَا بِٱلْيَوْمِ ٱلْـَٔاخِرِ وَلَا يُحَرِّمُونَ مَا حَرَّمَ ٱللَّهُ وَرَسُولُهُۥ وَلَا يَدِينُونَ دِينَ ٱلْحَقِّ مِنَ ٱلَّذِينَ أُوتُوا۟ ٱلْكِتَـٰبَ حَتَّىٰ يُعْطُوا۟ ٱلْجِزْيَةَ عَن يَدٍ وَهُمْ صَـٰغِرُونَ
Transliteration qātilū alladhīna lā yu'minūna bil-lahi walā bil-yawmi l-ākhiri walā yuḥarrimūna mā ḥarrama l-lahu warasūluhu walā yadīnūna dīna l-ḥaqi mina alladhīna ūtū l-kitāba ḥattā yuʿ'ṭū l-jiz'yata ʿan yadin wahum ṣāghirūna
Yoruba Ẹ gbógun ti àwọn tí kò gbàgbọ́ nínú Allāhu àti Ọjọ́ Ìkẹ́yìn àti àwọn tí kò ṣe ní èèwọ̀ ohun tí Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀ ṣe ní èèwọ̀àti àwọn tí kò ṣe ẹ̀sìn òdodo nínú àwọn tí A fún ní tírà. (Ẹ gbógun tì wọ́n) títí wọ́n yóò fi máa fi ọwọ́ ará wọn san owó-orí ní ẹni yẹpẹrẹ.
Verse 30
وَقَالَتِ ٱلْيَهُودُ عُزَيْرٌ ٱبْنُ ٱللَّهِ وَقَالَتِ ٱلنَّصَـٰرَى ٱلْمَسِيحُ ٱبْنُ ٱللَّهِ ۖ ذَٰلِكَ قَوْلُهُم بِأَفْوَٰهِهِمْ ۖ يُضَـٰهِـُٔونَ قَوْلَ ٱلَّذِينَ كَفَرُوا۟ مِن قَبْلُ ۚ قَـٰتَلَهُمُ ٱللَّهُ ۚ أَنَّىٰ يُؤْفَكُونَ
Transliteration waqālati l-yahūdu ʿuzayrun ub'nu l-lahi waqālati l-naṣārā l-masīḥu ub'nu l-lahi dhālika qawluhum bi-afwāhihim yuḍāhiūna qawla alladhīna kafarū min qablu qātalahumu l-lahu annā yu'fakūna
Yoruba Àwọn yẹhudi wí pé: “‘Uzaer ni ọmọ Allāhu.” Àwọn nasọ̄rọ̄ sì wí pé: “Mọsīh ni ọmọ Allāhu.” Ìyẹn ni ọ̀rọ̀ wọn ní ẹnu wọn. Wọ́n ń fi jọ ọ̀rọ̀ àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ ṣíwájú (wọn). Allāhu fi wọ́n gégùn-ún. Báwo ni wọ́n ṣe ń ṣẹ́rí wọn kúrò níbi òdodo!
Verse 31
ٱتَّخَذُوٓا۟ أَحْبَارَهُمْ وَرُهْبَـٰنَهُمْ أَرْبَابًا مِّن دُونِ ٱللَّهِ وَٱلْمَسِيحَ ٱبْنَ مَرْيَمَ وَمَآ أُمِرُوٓا۟ إِلَّا لِيَعْبُدُوٓا۟ إِلَـٰهًا وَٰحِدًا ۖ لَّآ إِلَـٰهَ إِلَّا هُوَ ۚ سُبْحَـٰنَهُۥ عَمَّا يُشْرِكُونَ
Transliteration ittakhadhū aḥbārahum waruh'bānahum arbāban min dūni l-lahi wal-masīḥa ib'na maryama wamā umirū illā liyaʿbudū ilāhan wāḥidan lā ilāha illā huwa sub'ḥānahu ʿammā yush'rikūna
Yoruba Wọ́n mú àwọn àlùfáà wọn (nínú yẹhudi) àti àwọn àlùfáà wọn (nínú nasọ̄rọ̄) ní olúwa lẹ́yìn Allāhu. (Wọ́n tún mú) Mọsīh ọmọ Mọryam (ní olúwa lẹ́yìn Allāhu). Bẹ́ẹ̀ sì ni A ò pa wọ́n láṣẹ kan tayọ jíjọ́sìn fún Ọlọ́hun, Ọ̀kan ṣoṣo. Kò sí ọlọ́hun kan tí a gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo àyàfi Òun. Ó mọ́ tayọ n̄ǹkan tí wọ́n ń fi ṣẹbọ sí I.
Verse 32
يُرِيدُونَ أَن يُطْفِـُٔوا۟ نُورَ ٱللَّهِ بِأَفْوَٰهِهِمْ وَيَأْبَى ٱللَّهُ إِلَّآ أَن يُتِمَّ نُورَهُۥ وَلَوْ كَرِهَ ٱلْكَـٰفِرُونَ
Transliteration yurīdūna an yuṭ'fiū nūra l-lahi bi-afwāhihim wayabā l-lahu illā an yutimma nūrahu walaw kariha l-kāfirūna
Yoruba Wọ́n fẹ́ fi ẹnu wọn pa ìmọ́lẹ̀ (ẹ̀sìn) Allāhu, Allāhu yó sì kọ̀ (fún wọn) títí Ó fi máa pé ìmọ́lẹ̀ (ẹ̀sìn) Rẹ̀, àwọn aláìgbàgbọ́ ìbáà kórira rẹ̀.
Verse 33
هُوَ ٱلَّذِىٓ أَرْسَلَ رَسُولَهُۥ بِٱلْهُدَىٰ وَدِينِ ٱلْحَقِّ لِيُظْهِرَهُۥ عَلَى ٱلدِّينِ كُلِّهِۦ وَلَوْ كَرِهَ ٱلْمُشْرِكُونَ
Transliteration huwa alladhī arsala rasūlahu bil-hudā wadīni l-ḥaqi liyuẓ'hirahu ʿalā l-dīni kullihi walaw kariha l-mush'rikūna
Yoruba (Allāhu) Òun ni Ẹni tí Ó fi ìmọ̀nà àti ẹ̀sìn òdodo (ẹ̀sìn ’Islām) rán Òjíṣẹ́ Rẹ̀ nítorí kí Ó lè fi borí gbogbo ẹ̀sìn (mìíràn) pátápátá, àwọn ọ̀ṣẹbọ ìbáà kórira rẹ̀.
Verse 34
۞ يَـٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُوٓا۟ إِنَّ كَثِيرًا مِّنَ ٱلْأَحْبَارِ وَٱلرُّهْبَانِ لَيَأْكُلُونَ أَمْوَٰلَ ٱلنَّاسِ بِٱلْبَـٰطِلِ وَيَصُدُّونَ عَن سَبِيلِ ٱللَّهِ ۗ وَٱلَّذِينَ يَكْنِزُونَ ٱلذَّهَبَ وَٱلْفِضَّةَ وَلَا يُنفِقُونَهَا فِى سَبِيلِ ٱللَّهِ فَبَشِّرْهُم بِعَذَابٍ أَلِيمٍ
Transliteration yāayyuhā alladhīna āmanū inna kathīran mina l-aḥbāri wal-ruh'bāni layakulūna amwāla l-nāsi bil-bāṭili wayaṣuddūna ʿan sabīli l-lahi wa-alladhīna yaknizūna l-dhahaba wal-fiḍata walā yunfiqūnahā fī sabīli l-lahi fabashir'hum biʿadhābin alīmin
Yoruba Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ nínú àwọn àlùfáà (nínú yẹhudi) àti àwọn àlùfáà (nínú nasọ̄rọ̄), wọ́n kúkú ń fi ọ̀nà èrú jẹ dúkìá àwọn ènìyàn ni, wọ́n sì ń ṣẹ́rí àwọn ènìyàn kúrò lójú ọ̀nà (ẹ̀sìn) Allāhu. Àwọn tó sì ń kó wúrà àti fàdákà jọ, wọn kò sì ná an fún ẹ̀sìn Allāhu, fún wọn ní ìró ìyà ẹlẹ́ta-eléro.
Verse 35
يَوْمَ يُحْمَىٰ عَلَيْهَا فِى نَارِ جَهَنَّمَ فَتُكْوَىٰ بِهَا جِبَاهُهُمْ وَجُنُوبُهُمْ وَظُهُورُهُمْ ۖ هَـٰذَا مَا كَنَزْتُمْ لِأَنفُسِكُمْ فَذُوقُوا۟ مَا كُنتُمْ تَكْنِزُونَ
Transliteration yawma yuḥ'mā ʿalayhā fī nāri jahannama fatuk'wā bihā jibāhuhum wajunūbuhum waẓuhūruhum hādhā mā kanaztum li-anfusikum fadhūqū mā kuntum taknizūna
Yoruba Ní ọjọ́ tí A óò máa yọ́ (wúrà àti fàdákà náà) nínú iná Jahanamọ, A ó sì máa fi jó iwájú wọn, ẹ̀gbẹ́ wọn àti ẹ̀yìn wọn. (A sì máa sọ pé): “Èyí ni ohun tí ẹ kó jọ fún ẹ̀mí ara yín. Nítorí náà, ẹ tọ́ ohun tí ẹ kó jọ wò.”
Verse 36
إِنَّ عِدَّةَ ٱلشُّهُورِ عِندَ ٱللَّهِ ٱثْنَا عَشَرَ شَهْرًا فِى كِتَـٰبِ ٱللَّهِ يَوْمَ خَلَقَ ٱلسَّمَـٰوَٰتِ وَٱلْأَرْضَ مِنْهَآ أَرْبَعَةٌ حُرُمٌ ۚ ذَٰلِكَ ٱلدِّينُ ٱلْقَيِّمُ ۚ فَلَا تَظْلِمُوا۟ فِيهِنَّ أَنفُسَكُمْ ۚ وَقَـٰتِلُوا۟ ٱلْمُشْرِكِينَ كَآفَّةً كَمَا يُقَـٰتِلُونَكُمْ كَآفَّةً ۚ وَٱعْلَمُوٓا۟ أَنَّ ٱللَّهَ مَعَ ٱلْمُتَّقِينَ
Transliteration inna ʿiddata l-shuhūri ʿinda l-lahi ith'nā ʿashara shahran fī kitābi l-lahi yawma khalaqa l-samāwāti wal-arḍa min'hā arbaʿatun ḥurumun dhālika l-dīnu l-qayimu falā taẓlimū fīhinna anfusakum waqātilū l-mush'rikīna kāffatan kamā yuqātilūnakum kāffatan wa-iʿ'lamū anna l-laha maʿa l-mutaqīna
Yoruba Dájúdájú òǹkà àwọn oṣù lọ́dọ̀ Allāhu ń jẹ́ oṣù méjìlá nínú àkọsílẹ̀ ti Allāhu ní ọjọ́ tí Ó ti dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Mẹ́rin ni oṣù ọ̀wọ̀ nínú rẹ̀.Ìyẹn ni ẹ̀sìn tó fẹsẹ̀ rinlẹ̀.2 Nítorí náà, ẹ má ṣàbòsí sí ara yín nínú àwọn oṣù ọ̀wọ̀. Kí gbogbo yín sì gbógun ti àwọn ọ̀ṣẹbọ gẹ́gẹ́ bí gbogbo wọn ṣe ń gbógun tì yín. Kí ẹ sì mọ̀ pé dájúdájú Allāhu wà pẹ̀lú àwọn olùbẹ̀rù (Rẹ̀).
Verse 37
إِنَّمَا ٱلنَّسِىٓءُ زِيَادَةٌ فِى ٱلْكُفْرِ ۖ يُضَلُّ بِهِ ٱلَّذِينَ كَفَرُوا۟ يُحِلُّونَهُۥ عَامًا وَيُحَرِّمُونَهُۥ عَامًا لِّيُوَاطِـُٔوا۟ عِدَّةَ مَا حَرَّمَ ٱللَّهُ فَيُحِلُّوا۟ مَا حَرَّمَ ٱللَّهُ ۚ زُيِّنَ لَهُمْ سُوٓءُ أَعْمَـٰلِهِمْ ۗ وَٱللَّهُ لَا يَهْدِى ٱلْقَوْمَ ٱلْكَـٰفِرِينَ
Transliteration innamā l-nasīu ziyādatun fī l-kuf'ri yuḍallu bihi alladhīna kafarū yuḥillūnahu ʿāman wayuḥarrimūnahu ʿāman liyuwāṭiū ʿiddata mā ḥarrama l-lahu fayuḥillū mā ḥarrama l-lahu zuyyina lahum sūu aʿmālihim wal-lahu lā yahdī l-qawma l-kāfirīna
Yoruba Àlékún nínú àìgbàgbọ́ ni dídájọ́ sí àwọn oṣù ọ̀wọ̀ (láti ọwọ́ àwọn ọ̀ṣẹbọ). Wọ́n ń fi kó ìṣìnà bá àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ (nípa pé) wọ́n ń ṣe oṣù ọ̀wọ̀ kan ní oṣù ẹ̀tọ́ (fún ogun jíjà) nínú ọdún kan, wọ́n sì ń bu ọ̀wọ̀ fún oṣù (tí kì í ṣe oṣù ọ̀wọ̀) nínú ọdún (mìíràn, wọn kò níí jagun nínú rẹ̀, wọ́n sì máa yọ òǹkà oṣù náà síra wọn) nítorí kí òǹkà tí Allāhu ṣe ní èèwọ̀ lè papọ̀ mọ́ra wọn (sínú àwọn oṣù tí kì í ṣe oṣù ọ̀wọ̀). Wọ́n sì tipasẹ̀ bẹ́ẹ̀ ṣe ní ẹ̀tọ́ ohun tí Allāhu ṣe ní èèwọ̀. Wọ́n ṣe iṣẹ́ aburú wọn ní ọ̀ṣọ́ fún wọn. Allāhu kò níí fi ọ̀nà mọ ìjọ aláìgbàgbọ́.
Verse 38
يَـٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُوا۟ مَا لَكُمْ إِذَا قِيلَ لَكُمُ ٱنفِرُوا۟ فِى سَبِيلِ ٱللَّهِ ٱثَّاقَلْتُمْ إِلَى ٱلْأَرْضِ ۚ أَرَضِيتُم بِٱلْحَيَوٰةِ ٱلدُّنْيَا مِنَ ٱلْـَٔاخِرَةِ ۚ فَمَا مَتَـٰعُ ٱلْحَيَوٰةِ ٱلدُّنْيَا فِى ٱلْـَٔاخِرَةِ إِلَّا قَلِيلٌ
Transliteration yāayyuhā alladhīna āmanū mā lakum idhā qīla lakumu infirū fī sabīli l-lahi ithāqaltum ilā l-arḍi araḍītum bil-ḥayati l-dun'yā mina l-ākhirati famā matāʿu l-ḥayati l-dun'yā fī l-ākhirati illā qalīlun
Yoruba Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, kí ni ó mu yín tí ó fi jẹ́ pé nígbà tí wọ́n bá sọ fún yín pé kí ẹ tú jáde (láti jagun) lójú ọ̀nà (ẹ̀sìn) Allāhu, (ìgbà náà ni) ẹ máa kàndí mọ́lẹ̀! Ṣé ẹ yọ́nú sí ìṣẹ̀mí ayé (yìí) ju ti ọ̀run ni? Ìgbádùn ìṣẹ̀mí ayé (yìí) kò sì jẹ́ kiní kan nínú ti ọ̀run àfi díẹ̀.
Verse 39
إِلَّا تَنفِرُوا۟ يُعَذِّبْكُمْ عَذَابًا أَلِيمًا وَيَسْتَبْدِلْ قَوْمًا غَيْرَكُمْ وَلَا تَضُرُّوهُ شَيْـًٔا ۗ وَٱللَّهُ عَلَىٰ كُلِّ شَىْءٍ قَدِيرٌ
Transliteration illā tanfirū yuʿadhib'kum ʿadhāban alīman wayastabdil qawman ghayrakum walā taḍurrūhu shayan wal-lahu ʿalā kulli shayin qadīrun
Yoruba Àfi kí ẹ tú jáde (sógun ẹ̀sìn) ni Allāhu kò fi níí jẹ yín níyà ẹlẹ́ta-eléro àti pé ni kò fi níí fi ìjọ tó yàtọ̀ si yín pààrọ̀ yín. Ẹ kò sì lè fi kiní kan kó ìnira bá (Allāhu). Allāhu sì ni Alagbára lórí gbogbo n̄ǹkan.
Verse 40
إِلَّا تَنصُرُوهُ فَقَدْ نَصَرَهُ ٱللَّهُ إِذْ أَخْرَجَهُ ٱلَّذِينَ كَفَرُوا۟ ثَانِىَ ٱثْنَيْنِ إِذْ هُمَا فِى ٱلْغَارِ إِذْ يَقُولُ لِصَـٰحِبِهِۦ لَا تَحْزَنْ إِنَّ ٱللَّهَ مَعَنَا ۖ فَأَنزَلَ ٱللَّهُ سَكِينَتَهُۥ عَلَيْهِ وَأَيَّدَهُۥ بِجُنُودٍ لَّمْ تَرَوْهَا وَجَعَلَ كَلِمَةَ ٱلَّذِينَ كَفَرُوا۟ ٱلسُّفْلَىٰ ۗ وَكَلِمَةُ ٱللَّهِ هِىَ ٱلْعُلْيَا ۗ وَٱللَّهُ عَزِيزٌ حَكِيمٌ
Transliteration illā tanṣurūhu faqad naṣarahu l-lahu idh akhrajahu alladhīna kafarū thāniya ith'nayni idh humā fī l-ghāri idh yaqūlu liṣāḥibihi lā taḥzan inna l-laha maʿanā fa-anzala l-lahu sakīnatahu ʿalayhi wa-ayyadahu bijunūdin lam tarawhā wajaʿala kalimata alladhīna kafarū l-suf'lā wakalimatu l-lahi hiya l-ʿul'yā wal-lahu ʿazīzun ḥakīmun
Yoruba Àfi kí ẹ ràn án lọ́wọ́, Allāhu kúkú ti ràn án lọ́wọ́ nígbà tí àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ lé e jáde (kúrò nínú ìlú). Ó sì jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn méjì.Nígbà tí àwọn méjèèjì wà nínú ọ̀gbun, tí (Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -) sì ń sọ fún olùbárìn rẹ̀ pé: “Má ṣe banújẹ́, dájúdájú Allāhu wà pẹ̀lú wa.”2 Nígbà náà, Allāhu sọ ìfàyàbalẹ̀ Rẹ̀ kalẹ̀ fún un. Ó fi àwọn ọmọ ogun kan tí ẹ kò fojú rí ràn án lọ́wọ́. Ó sì mú ọ̀rọ̀ àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ wálẹ̀. Ọ̀rọ̀ Allāhu, òhun ló sì lékè. Allāhu sì ni Alágbára, Ọlọ́gbọ́n.
Verse 41
ٱنفِرُوا۟ خِفَافًا وَثِقَالًا وَجَـٰهِدُوا۟ بِأَمْوَٰلِكُمْ وَأَنفُسِكُمْ فِى سَبِيلِ ٱللَّهِ ۚ ذَٰلِكُمْ خَيْرٌ لَّكُمْ إِن كُنتُمْ تَعْلَمُونَ
Transliteration infirū khifāfan wathiqālan wajāhidū bi-amwālikum wa-anfusikum fī sabīli l-lahi dhālikum khayrun lakum in kuntum taʿlamūna
Yoruba Ẹ tú jáde (fún ogun ẹ̀sìn) pẹ̀lú okun àti ìrọ́jú. Kí ẹ sì fi àwọn dúkìá yín àti ẹ̀mí yin jagun fún ẹ̀sìn Allāhu. Ìyẹn lóore jùlọ fún yín tí ẹ bá mọ̀.
Verse 42
لَوْ كَانَ عَرَضًا قَرِيبًا وَسَفَرًا قَاصِدًا لَّٱتَّبَعُوكَ وَلَـٰكِنۢ بَعُدَتْ عَلَيْهِمُ ٱلشُّقَّةُ ۚ وَسَيَحْلِفُونَ بِٱللَّهِ لَوِ ٱسْتَطَعْنَا لَخَرَجْنَا مَعَكُمْ يُهْلِكُونَ أَنفُسَهُمْ وَٱللَّهُ يَعْلَمُ إِنَّهُمْ لَكَـٰذِبُونَ
Transliteration law kāna ʿaraḍan qarīban wasafaran qāṣidan la-ittabaʿūka walākin baʿudat ʿalayhimu l-shuqatu wasayaḥlifūna bil-lahi lawi is'taṭaʿnā lakharajnā maʿakum yuh'likūna anfusahum wal-lahu yaʿlamu innahum lakādhibūna
Yoruba Tí ó bá jẹ́ pé n̄ǹkan ìgbádùn (ọrọ̀ ogun) àrọ́wótó àti ìrìn-àjò tí kò jìnnà (lo pè wọ́n sí ni), wọn ìbá tẹ̀lé ọ. Ṣùgbọ́n ìrìn-àjò tó lágbára (ti t'ogun Tabūk) jìnnà lójú wọn. Wọ́n yó sì máa fi Allāhu búra pé: “Tí ó bá jẹ́ pé a lágbára ni, àwa ìbá jáde (fún ogun ẹ̀sìn) pẹ̀lú yín.” - Wọ́n sì ń kó ìparun bá ẹ̀mí ara wọn (nípa ṣíṣe ìṣọ̀bẹ-ṣèlu.) - Allāhu sì mọ̀ pé dájúdájú òpùrọ́ ni wọ́n.
Verse 43
عَفَا ٱللَّهُ عَنكَ لِمَ أَذِنتَ لَهُمْ حَتَّىٰ يَتَبَيَّنَ لَكَ ٱلَّذِينَ صَدَقُوا۟ وَتَعْلَمَ ٱلْكَـٰذِبِينَ
Transliteration ʿafā l-lahu ʿanka lima adhinta lahum ḥattā yatabayyana laka alladhīna ṣadaqū wataʿlama l-kādhibīna
Yoruba Allāhu ti ṣàmójúkúrò fún ọ. Kí ló mú ọ yọ̀ǹda fún wọn (pé kí wọ́n dúró sílé? Ìwọ ìbá má ṣe bẹ́ẹ̀) títí ọ̀rọ̀ àwọn tó sòdodo yóò fi hàn sí ọ kedere. Ìwọ yó sì mọ àwọn òpùrọ́.
Verse 44
لَا يَسْتَـْٔذِنُكَ ٱلَّذِينَ يُؤْمِنُونَ بِٱللَّهِ وَٱلْيَوْمِ ٱلْـَٔاخِرِ أَن يُجَـٰهِدُوا۟ بِأَمْوَٰلِهِمْ وَأَنفُسِهِمْ ۗ وَٱللَّهُ عَلِيمٌۢ بِٱلْمُتَّقِينَ
Transliteration lā yastadhinuka alladhīna yu'minūna bil-lahi wal-yawmi l-ākhiri an yujāhidū bi-amwālihim wa-anfusihim wal-lahu ʿalīmun bil-mutaqīna
Yoruba Àwọn tó gbàgbọ́ nínú Allāhu àti Ọjọ́ Ìkẹ́yìn kò níí tọrọ ìyọ̀ǹda lọ́dọ̀ rẹ láti má fi dúkìá wọn àti ẹ̀mí wọn jagun fún ẹ̀sìn Allāhu. Allāhu sì ni Onímọ̀ nípa àwọn olùbẹ̀rù (Rẹ̀).
Verse 45
إِنَّمَا يَسْتَـْٔذِنُكَ ٱلَّذِينَ لَا يُؤْمِنُونَ بِٱللَّهِ وَٱلْيَوْمِ ٱلْـَٔاخِرِ وَٱرْتَابَتْ قُلُوبُهُمْ فَهُمْ فِى رَيْبِهِمْ يَتَرَدَّدُونَ
Transliteration innamā yastadhinuka alladhīna lā yu'minūna bil-lahi wal-yawmi l-ākhiri wa-ir'tābat qulūbuhum fahum fī raybihim yataraddadūna
Yoruba Àwọn tó ń tọrọ ìyọ̀ǹda lọ́dọ̀ rẹ (láti jókòó sílé, dípò lílọ sí ojú-ogun) ni àwọn tí kò gbàgbọ́ nínú Allāhu àti Ọjọ́ Ìkẹ́yìn; ọkan wọn sì ń ṣeyèméjì. Nítorí náà, wọ́n ń dààmú kiri níbi ìṣeyè-méjì wọn.
Verse 46
۞ وَلَوْ أَرَادُوا۟ ٱلْخُرُوجَ لَأَعَدُّوا۟ لَهُۥ عُدَّةً وَلَـٰكِن كَرِهَ ٱللَّهُ ٱنۢبِعَاثَهُمْ فَثَبَّطَهُمْ وَقِيلَ ٱقْعُدُوا۟ مَعَ ٱلْقَـٰعِدِينَ
Transliteration walaw arādū l-khurūja la-aʿaddū lahu ʿuddatan walākin kariha l-lahu inbiʿāthahum fathabbaṭahum waqīla uq'ʿudū maʿa l-qāʿidīna
Yoruba Tí ó bá jẹ́ pé wọn gbèrò ìjáde fún ogun ẹ̀sìn ni, wọn ìbá ṣe ìpalẹ̀mọ́ fún un. Ṣùgbọ́n Allāhu kórira ìdìde wọn fún ogun ẹ̀sìn, Ó sì kó ìfàsẹ́yìn bá wọn. Wọ́n sì sọ fún wọn pé: “Ẹ jókòó pẹ̀lú àwọn olùjókòó sílé.”
Verse 47
لَوْ خَرَجُوا۟ فِيكُم مَّا زَادُوكُمْ إِلَّا خَبَالًا وَلَأَوْضَعُوا۟ خِلَـٰلَكُمْ يَبْغُونَكُمُ ٱلْفِتْنَةَ وَفِيكُمْ سَمَّـٰعُونَ لَهُمْ ۗ وَٱللَّهُ عَلِيمٌۢ بِٱلظَّـٰلِمِينَ
Transliteration law kharajū fīkum mā zādūkum illā khabālan wala-awḍaʿū khilālakum yabghūnakumu l-fit'nata wafīkum sammāʿūna lahum wal-lahu ʿalīmun bil-ẓālimīna
Yoruba Tí ó bá jẹ́ pé wọ́n jáde pẹ̀lú yín, wọn kò níí kun yín àfi pẹ̀lú ìbàjẹ́. Wọn yó sì sáré máa dá rúkèrúdò sílẹ̀ láààrin yín, tí wọn yóò máa ko yín sínú ìyọnu. Àti pé wọ́n ní olùgbọ́rọ̀ fún wọn láààrin yín. Allāhu sì ni Onímọ̀ nípa àwọn alábòsí.
Verse 48
لَقَدِ ٱبْتَغَوُا۟ ٱلْفِتْنَةَ مِن قَبْلُ وَقَلَّبُوا۟ لَكَ ٱلْأُمُورَ حَتَّىٰ جَآءَ ٱلْحَقُّ وَظَهَرَ أَمْرُ ٱللَّهِ وَهُمْ كَـٰرِهُونَ
Transliteration laqadi ib'taghawū l-fit'nata min qablu waqallabū laka l-umūra ḥattā jāa l-ḥaqu waẓahara amru l-lahi wahum kārihūna
Yoruba Wọ́n kúkú ti wá ìyọnu tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀, wọ́n sì fimú fínlẹ̀ sì ọ (tí wọ́n dete sì ọ) títí òdodo fi dé, tí àṣẹ Allāhu sì borí; ẹ̀mí wọn sì kórira rẹ̀.
Verse 49
وَمِنْهُم مَّن يَقُولُ ٱئْذَن لِّى وَلَا تَفْتِنِّىٓ ۚ أَلَا فِى ٱلْفِتْنَةِ سَقَطُوا۟ ۗ وَإِنَّ جَهَنَّمَ لَمُحِيطَةٌۢ بِٱلْكَـٰفِرِينَ
Transliteration wamin'hum man yaqūlu i'dhan lī walā taftinnī alā fī l-fit'nati saqaṭū wa-inna jahannama lamuḥīṭatun bil-kāfirīna
Yoruba Ó wà nínú wọn, ẹni tí ń wí pé: “Yọ̀ǹda fún mi (kí n̄g jókòó sílé); má ṣe kó mi sínú àdánwò.” Inú àdánwò (sísá fógun ẹ̀sìn) má ni wọ́n ti ṣubú sí yìí. Dájúdájú iná Jahanamọ yó sì kúkú yí àwọn aláìgbàgbọ́ po.
Verse 50
إِن تُصِبْكَ حَسَنَةٌ تَسُؤْهُمْ ۖ وَإِن تُصِبْكَ مُصِيبَةٌ يَقُولُوا۟ قَدْ أَخَذْنَآ أَمْرَنَا مِن قَبْلُ وَيَتَوَلَّوا۟ وَّهُمْ فَرِحُونَ
Transliteration in tuṣib'ka ḥasanatun tasu'hum wa-in tuṣib'ka muṣībatun yaqūlū qad akhadhnā amranā min qablu wayatawallaw wahum fariḥūna
Yoruba Tí dáadáa kan bá ṣẹlẹ̀ sí ọ, ó máa bà wọ́n nínú jẹ́. Tí aburú kan bá sì ṣẹlẹ̀ sí ọ, wọ́n á wí pé: “A kúkú ti gba àṣẹ tiwa ṣíwájú (láti jókòó sílé.)” Wọ́n á pẹ̀yìn dà; wọn yó sì máa dunnú.
Verse 51
قُل لَّن يُصِيبَنَآ إِلَّا مَا كَتَبَ ٱللَّهُ لَنَا هُوَ مَوْلَىٰنَا ۚ وَعَلَى ٱللَّهِ فَلْيَتَوَكَّلِ ٱلْمُؤْمِنُونَ
Transliteration qul lan yuṣībanā illā mā kataba l-lahu lanā huwa mawlānā waʿalā l-lahi falyatawakkali l-mu'minūna
Yoruba Sọ pé: “Kò sí ohun kan tó máa ṣẹlẹ̀ sí wa àyàfi ohun tí Allāhu kọ mọ́ wa. Òun ni Aláàbò wa.” Allāhu sì ni kí àwọn onígbàgbọ́ òdodo gbáralé.
Verse 52
قُلْ هَلْ تَرَبَّصُونَ بِنَآ إِلَّآ إِحْدَى ٱلْحُسْنَيَيْنِ ۖ وَنَحْنُ نَتَرَبَّصُ بِكُمْ أَن يُصِيبَكُمُ ٱللَّهُ بِعَذَابٍ مِّنْ عِندِهِۦٓ أَوْ بِأَيْدِينَا ۖ فَتَرَبَّصُوٓا۟ إِنَّا مَعَكُم مُّتَرَبِّصُونَ
Transliteration qul hal tarabbaṣūna binā illā iḥ'dā l-ḥus'nayayni wanaḥnu natarabbaṣu bikum an yuṣībakumu l-lahu biʿadhābin min ʿindihi aw bi-aydīnā fatarabbaṣū innā maʿakum mutarabbiṣūna
Yoruba Sọ pé: “Ṣé ẹ̀ ń retí kiní kan pẹ̀lú wa ni bí kò ṣe ọ̀kan nínú dáadáa méjì (ikú ogun tàbí ìṣẹ́gun)? Àwa náà ń retí pẹ̀lú yín pé kí Allāhu mú ìyà kan wá ba yín láti ọ̀dọ̀ Rẹ̀ tàbí láti ọwọ́ wa. Nítorí náà, ẹ máa retí, dájúdájú àwa náà wà pẹ̀lú yín tí à ń retí.”
Verse 53
قُلْ أَنفِقُوا۟ طَوْعًا أَوْ كَرْهًا لَّن يُتَقَبَّلَ مِنكُمْ ۖ إِنَّكُمْ كُنتُمْ قَوْمًا فَـٰسِقِينَ
Transliteration qul anfiqū ṭawʿan aw karhan lan yutaqabbala minkum innakum kuntum qawman fāsiqīna
Yoruba Sọ pé: “Ẹ fínnú-fíndọ̀ náwó ni tàbí pẹ̀lú tipátipá, A ò níí gbà á lọ́wọ́ yín (nítorí pé) dájúdájú ẹ̀yin jẹ́ ìjọ òbìlẹ̀jẹ́.”
Verse 54
وَمَا مَنَعَهُمْ أَن تُقْبَلَ مِنْهُمْ نَفَقَـٰتُهُمْ إِلَّآ أَنَّهُمْ كَفَرُوا۟ بِٱللَّهِ وَبِرَسُولِهِۦ وَلَا يَأْتُونَ ٱلصَّلَوٰةَ إِلَّا وَهُمْ كُسَالَىٰ وَلَا يُنفِقُونَ إِلَّا وَهُمْ كَـٰرِهُونَ
Transliteration wamā manaʿahum an tuq'bala min'hum nafaqātuhum illā annahum kafarū bil-lahi wabirasūlihi walā yatūna l-ṣalata illā wahum kusālā walā yunfiqūna illā wahum kārihūna
Yoruba Kò sì sí ohun kan tí kò jẹ́ kí Á gba ìnáwó wọn lọ́wọ́ wọn bí kò ṣe pé dájúdájú wọ́n ṣàì gbàgbọ́ nínú Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀. Wọn kò níí wá kírun àfi kí wọ́n jẹ́ òròjú aláìníkan-ánṣe. Wọn kò sì níí náwó fẹ́sìn àfi kí ẹ̀mí wọn kórira rẹ̀.
Verse 55
فَلَا تُعْجِبْكَ أَمْوَٰلُهُمْ وَلَآ أَوْلَـٰدُهُمْ ۚ إِنَّمَا يُرِيدُ ٱللَّهُ لِيُعَذِّبَهُم بِهَا فِى ٱلْحَيَوٰةِ ٱلدُّنْيَا وَتَزْهَقَ أَنفُسُهُمْ وَهُمْ كَـٰفِرُونَ
Transliteration falā tuʿ'jib'ka amwāluhum walā awlāduhum innamā yurīdu l-lahu liyuʿadhibahum bihā fī l-ḥayati l-dun'yā watazhaqa anfusuhum wahum kāfirūna
Yoruba Nítorí náà, má ṣe jẹ́ kí àwọn dúkìá wọn àti àwọn ọmọ wọn jọ ọ́ lójú; Allāhu kàn fẹ́ fi jẹ wọ́n níyà nínú ìṣẹ̀mí ayé (yìí) ni. Ẹ̀mí yó sì bọ́ lára wọn, tí wọ́n máa wà nípò aláìgbàgbọ́.
Verse 56
وَيَحْلِفُونَ بِٱللَّهِ إِنَّهُمْ لَمِنكُمْ وَمَا هُم مِّنكُمْ وَلَـٰكِنَّهُمْ قَوْمٌ يَفْرَقُونَ
Transliteration wayaḥlifūna bil-lahi innahum laminkum wamā hum minkum walākinnahum qawmun yafraqūna
Yoruba Wọ́n ń fi Allāhu búra pé dájúdájú àwọn kúkú wà lára yín. Wọn kò sì sí lára yín, ṣùgbọ́n dájúdájú wọ́n jẹ́ ìjọ kan tó ń bẹ̀rù.1
Verse 57
لَوْ يَجِدُونَ مَلْجَـًٔا أَوْ مَغَـٰرَٰتٍ أَوْ مُدَّخَلًا لَّوَلَّوْا۟ إِلَيْهِ وَهُمْ يَجْمَحُونَ
Transliteration law yajidūna malja-an aw maghārātin aw muddakhalan lawallaw ilayhi wahum yajmaḥūna
Yoruba Tí ó bá jẹ́ pé wọ́n rí ibùsásí kan, tàbí àwọn ihò àpáta kan, tàbí ibùsáwọ̀ kan, wọn ìbá ṣẹ́rí síbẹ̀ ní wéréwéré.
Verse 58
وَمِنْهُم مَّن يَلْمِزُكَ فِى ٱلصَّدَقَـٰتِ فَإِنْ أُعْطُوا۟ مِنْهَا رَضُوا۟ وَإِن لَّمْ يُعْطَوْا۟ مِنْهَآ إِذَا هُمْ يَسْخَطُونَ
Transliteration wamin'hum man yalmizuka fī l-ṣadaqāti fa-in uʿ'ṭū min'hā raḍū wa-in lam yuʿ'ṭaw min'hā idhā hum yaskhaṭūna
Yoruba Ó tún wà nínú wọn, ẹni tí ń bú ọ níbi (pípín) àwọn ọrẹ. Tí A bá fún wọn nínú rẹ̀, wọ́n á yọ́nú (sí i). Tí A ò bá sì fún wọn nínú rẹ̀, nígbà náà ni wọn yóò máa bínú.
Verse 59
وَلَوْ أَنَّهُمْ رَضُوا۟ مَآ ءَاتَىٰهُمُ ٱللَّهُ وَرَسُولُهُۥ وَقَالُوا۟ حَسْبُنَا ٱللَّهُ سَيُؤْتِينَا ٱللَّهُ مِن فَضْلِهِۦ وَرَسُولُهُۥٓ إِنَّآ إِلَى ٱللَّهِ رَٰغِبُونَ
Transliteration walaw annahum raḍū mā ātāhumu l-lahu warasūluhu waqālū ḥasbunā l-lahu sayu'tīnā l-lahu min faḍlihi warasūluhu innā ilā l-lahi rāghibūna
Yoruba Àti pé (ìbá lóore fún wọn) tí ó bá jẹ́ pé dájúdájú wọ́n yọ́nú sí ohun tí Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀ fún wọn, kí wọ́n sì sọ pé: “Allāhu tó wa. Allāhu yó sì fún wa nínú oore àjùlọ Rẹ̀ àti pé Òjíṣẹ́ Rẹ̀ (sì máa pín ọrẹ) dájúdájú ọ̀dọ̀ Allāhu sì ni àwa ń wá oore sí.”
Verse 60
۞ إِنَّمَا ٱلصَّدَقَـٰتُ لِلْفُقَرَآءِ وَٱلْمَسَـٰكِينِ وَٱلْعَـٰمِلِينَ عَلَيْهَا وَٱلْمُؤَلَّفَةِ قُلُوبُهُمْ وَفِى ٱلرِّقَابِ وَٱلْغَـٰرِمِينَ وَفِى سَبِيلِ ٱللَّهِ وَٱبْنِ ٱلسَّبِيلِ ۖ فَرِيضَةً مِّنَ ٱللَّهِ ۗ وَٱللَّهُ عَلِيمٌ حَكِيمٌ
Transliteration innamā l-ṣadaqātu lil'fuqarāi wal-masākīni wal-ʿāmilīna ʿalayhā wal-mu-alafati qulūbuhum wafī l-riqābi wal-ghārimīna wafī sabīli l-lahi wa-ib'ni l-sabīli farīḍatan mina l-lahi wal-lahu ʿalīmun ḥakīmun
Yoruba Àwọn tí ọrẹ (Zakāh) wà fún ni àwọn aláìní, àwọn mẹ̀kúnnù,àwọn òṣìṣẹ́ Zakāh, àwọn tí ọkàn wọn fẹ́ gba ’Islām (ìyẹn àwọn tí wọ́n fẹ́ fi fa ọkàn wọn mọ́ra sínú ẹ̀sìn), àwọn ẹrú (fún gbígba òmìnira), àwọn onígbèsè, àwọn tó wà lójú ogun (ẹ̀sìn) Allāhu àti onírìn-àjò (tí agara dá). Ọ̀ran-anyàn ni láti ọ̀dọ̀ Allāhu. Allāhu sì ni Onímọ̀, Ọlọ́gbọ́n.
Verse 61
وَمِنْهُمُ ٱلَّذِينَ يُؤْذُونَ ٱلنَّبِىَّ وَيَقُولُونَ هُوَ أُذُنٌ ۚ قُلْ أُذُنُ خَيْرٍ لَّكُمْ يُؤْمِنُ بِٱللَّهِ وَيُؤْمِنُ لِلْمُؤْمِنِينَ وَرَحْمَةٌ لِّلَّذِينَ ءَامَنُوا۟ مِنكُمْ ۚ وَٱلَّذِينَ يُؤْذُونَ رَسُولَ ٱللَّهِ لَهُمْ عَذَابٌ أَلِيمٌ
Transliteration wamin'humu alladhīna yu'dhūna l-nabiya wayaqūlūna huwa udhunun qul udhunu khayrin lakum yu'minu bil-lahi wayu'minu lil'mu'minīna waraḥmatun lilladhīna āmanū minkum wa-alladhīna yu'dhūna rasūla l-lahi lahum ʿadhābun alīmun
Yoruba Àwọn tó ń kó ìnira bá Ànábì wà nínú wọn, tí wọ́n sì ń wí pé: “Elétí-ọfẹ ni.” Sọ pé: “Elétí-ọfẹ rere ni fún yín; ó gbàgbọ́ nínú Allāhu. Ó sì gba àwọn onígbàgbọ́ òdodo gbọ́. Ìkẹ́ ni fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo nínú yín. Àti pé àwọn tó ń kó ìnira bá Òjíṣẹ́ Allāhu, ìyà ẹlẹ́ta-eléro ń bẹ fún wọn.”
Verse 62
يَحْلِفُونَ بِٱللَّهِ لَكُمْ لِيُرْضُوكُمْ وَٱللَّهُ وَرَسُولُهُۥٓ أَحَقُّ أَن يُرْضُوهُ إِن كَانُوا۟ مُؤْمِنِينَ
Transliteration yaḥlifūna bil-lahi lakum liyur'ḍūkum wal-lahu warasūluhu aḥaqqu an yur'ḍūhu in kānū mu'minīna
Yoruba Wọ́n ń fi Allāhu búra fún yín láti wá ìyọ́nú yín. Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀ ló sì lẹ́tọ̀ọ́ jùlọ pe kí wọ́n wá ìyọ́nú Rẹ̀ tí wọ́n bá jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo.
Verse 63
أَلَمْ يَعْلَمُوٓا۟ أَنَّهُۥ مَن يُحَادِدِ ٱللَّهَ وَرَسُولَهُۥ فَأَنَّ لَهُۥ نَارَ جَهَنَّمَ خَـٰلِدًا فِيهَا ۚ ذَٰلِكَ ٱلْخِزْىُ ٱلْعَظِيمُ
Transliteration alam yaʿlamū annahu man yuḥādidi l-laha warasūlahu fa-anna lahu nāra jahannama khālidan fīhā dhālika l-khiz'yu l-ʿaẓīmu
Yoruba Ṣé wọn kò mọ̀ pé dájúdájú ẹnikẹ́ni tó bá ń tako Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀, dájúdájú iná Jahanamọ ti wà fún un ni? Olùṣegbére sì ni nínú rẹ̀. Ìyẹn sì ni àbùkù ńlá.
Verse 64
يَحْذَرُ ٱلْمُنَـٰفِقُونَ أَن تُنَزَّلَ عَلَيْهِمْ سُورَةٌ تُنَبِّئُهُم بِمَا فِى قُلُوبِهِمْ ۚ قُلِ ٱسْتَهْزِءُوٓا۟ إِنَّ ٱللَّهَ مُخْرِجٌ مَّا تَحْذَرُونَ
Transliteration yaḥdharu l-munāfiqūna an tunazzala ʿalayhim sūratun tunabbi-uhum bimā fī qulūbihim quli is'tahziū inna l-laha mukh'rijun mā taḥdharūna
Yoruba Àwọn ṣọ̀bẹ-ṣèlu mùsùlùmí ń bẹ̀rù pé kí Á má ṣe sọ sūrah kan kalẹ̀ nípa wọn, tí ó máa fún wọn ní ìró ohun tí ń bẹ nínú ọkàn wọn. Sọ pé: “Ẹ máa ṣe yẹ̀yẹ́ lọ. Dájúdájú Allāhu yóò ṣàfi hàn ohun tí ẹ̀ ń bẹ̀rù.”
Verse 65
وَلَئِن سَأَلْتَهُمْ لَيَقُولُنَّ إِنَّمَا كُنَّا نَخُوضُ وَنَلْعَبُ ۚ قُلْ أَبِٱللَّهِ وَءَايَـٰتِهِۦ وَرَسُولِهِۦ كُنتُمْ تَسْتَهْزِءُونَ
Transliteration wala-in sa-altahum layaqūlunna innamā kunnā nakhūḍu wanalʿabu qul abil-lahi waāyātihi warasūlihi kuntum tastahziūna
Yoruba Tí o bá kúkú bi wọ́n léèrè, dájúdájú wọ́n á wí pé: “Àwa kàn ń rojọ́ lásán ni, a sì ń ṣàwàdà ni.” Sọ pé: “Ṣé Allāhu, àwọn āyah Rẹ̀ àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀ ni ẹ̀ ń fi ṣe yẹ̀yẹ́?”
Verse 66
لَا تَعْتَذِرُوا۟ قَدْ كَفَرْتُم بَعْدَ إِيمَـٰنِكُمْ ۚ إِن نَّعْفُ عَن طَآئِفَةٍ مِّنكُمْ نُعَذِّبْ طَآئِفَةًۢ بِأَنَّهُمْ كَانُوا۟ مُجْرِمِينَ
Transliteration lā taʿtadhirū qad kafartum baʿda īmānikum in naʿfu ʿan ṭāifatin minkum nuʿadhib ṭāifatan bi-annahum kānū muj'rimīna
Yoruba Ẹ má ṣe mú àwáwí wá. Dájúdájú ẹ ti ṣàì gbàgbọ́ lẹ́yìn ìgbàgbọ́ yín. Tí A bá ṣe àmójúkúrò fún apá kan nínú yín, A óò fìyà jẹ apá kan nítorí pé wọ́n jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀.
Verse 67
ٱلْمُنَـٰفِقُونَ وَٱلْمُنَـٰفِقَـٰتُ بَعْضُهُم مِّنۢ بَعْضٍ ۚ يَأْمُرُونَ بِٱلْمُنكَرِ وَيَنْهَوْنَ عَنِ ٱلْمَعْرُوفِ وَيَقْبِضُونَ أَيْدِيَهُمْ ۚ نَسُوا۟ ٱللَّهَ فَنَسِيَهُمْ ۗ إِنَّ ٱلْمُنَـٰفِقِينَ هُمُ ٱلْفَـٰسِقُونَ
Transliteration al-munāfiqūna wal-munāfiqātu baʿḍuhum min baʿḍin yamurūna bil-munkari wayanhawna ʿani l-maʿrūfi wayaqbiḍūna aydiyahum nasū l-laha fanasiyahum inna l-munāfiqīna humu l-fāsiqūna
Yoruba Àwọn ṣọ̀bẹ-ṣèlu mùsùlùmí lọ́kùnrin àti àwọn ṣọ̀bẹ-ṣèlu mùsùlùmọ́ lóbìnrin, irú kan-ùn ni wọ́n; wọ́n ń pàṣẹ ohun burúkú, wọ́n ń kọ ohun rere, wọ́n sì ń káwọ́ gbera (láti náwó fẹ́sìn). Wọ́n gbàgbé Allāhu. Nítorí náà, Allāhu gbàgbé wọn.Dájúdájú àwọn ṣọ̀bẹ-ṣèlu mùsùlùmí, àwọn ni òbìlẹ̀jẹ́.
Verse 68
وَعَدَ ٱللَّهُ ٱلْمُنَـٰفِقِينَ وَٱلْمُنَـٰفِقَـٰتِ وَٱلْكُفَّارَ نَارَ جَهَنَّمَ خَـٰلِدِينَ فِيهَا ۚ هِىَ حَسْبُهُمْ ۚ وَلَعَنَهُمُ ٱللَّهُ ۖ وَلَهُمْ عَذَابٌ مُّقِيمٌ
Transliteration waʿada l-lahu l-munāfiqīna wal-munāfiqāti wal-kufāra nāra jahannama khālidīna fīhā hiya ḥasbuhum walaʿanahumu l-lahu walahum ʿadhābun muqīmun
Yoruba Allāhu sì ti ṣe àdéhùn iná Jahanamọ fún àwọn ṣọ̀bẹ-ṣèlu mùsùlùmí lọ́kùnrin àti àwọn ṣọ̀bẹ-ṣèlu mùsùlùmọ́ lóbìnrin àti àwọn aláìgbàgbọ́. Olùṣegbére ni wọn nínú rẹ̀. Iná máa tó wọn. Allāhu sì ti ṣẹ́bi lé wọn. Ìyà gbére sì wà fún wọn.
Verse 69
كَٱلَّذِينَ مِن قَبْلِكُمْ كَانُوٓا۟ أَشَدَّ مِنكُمْ قُوَّةً وَأَكْثَرَ أَمْوَٰلًا وَأَوْلَـٰدًا فَٱسْتَمْتَعُوا۟ بِخَلَـٰقِهِمْ فَٱسْتَمْتَعْتُم بِخَلَـٰقِكُمْ كَمَا ٱسْتَمْتَعَ ٱلَّذِينَ مِن قَبْلِكُم بِخَلَـٰقِهِمْ وَخُضْتُمْ كَٱلَّذِى خَاضُوٓا۟ ۚ أُو۟لَـٰٓئِكَ حَبِطَتْ أَعْمَـٰلُهُمْ فِى ٱلدُّنْيَا وَٱلْـَٔاخِرَةِ ۖ وَأُو۟لَـٰٓئِكَ هُمُ ٱلْخَـٰسِرُونَ
Transliteration ka-alladhīna min qablikum kānū ashadda minkum quwwatan wa-akthara amwālan wa-awlādan fa-is'tamtaʿū bikhalāqihim fa-is'tamtaʿtum bikhalāqikum kamā is'tamtaʿa alladhīna min qablikum bikhalāqihim wakhuḍ'tum ka-alladhī khāḍū ulāika ḥabiṭat aʿmāluhum fī l-dun'yā wal-ākhirati wa-ulāika humu l-khāsirūna
Yoruba (Àwọn ṣọ̀bẹ-ṣèlu mùsùlùmí dà) gẹ́gẹ́ bí àwọn tó ṣíwájú yín; wọ́n le jù yín lọ ní agbára, wọ́n sì pọ̀ (jù yín lọ) ní àwọn dúkìá àti àwọn ọmọ. Nígbà náà, wọ́n jẹ ìgbádùn ìpín tiwọn (nínú oore ayé). Ẹ̀yin (ṣọ̀bẹ-ṣèlu wọ̀nyìí náà yóò) jẹ ìgbádùn ìpín tiyín gẹ́gẹ́ bí àwọn tó ṣíwájú yín ṣe jẹ ìgbádùn ìpín tiwọn. Ẹ̀yin náà sì sọ̀sọkúsọ bí èyí tí àwọn náà sọ ní ìsọkúsọ. Àwọn wọ̀nyẹn, àwọn iṣẹ́ wọn ti bàjẹ́ ní ayé àti ní ọ̀run. Àwọn wọ̀nyẹn, àwọn sì ni ẹni òfò.
Verse 70
أَلَمْ يَأْتِهِمْ نَبَأُ ٱلَّذِينَ مِن قَبْلِهِمْ قَوْمِ نُوحٍ وَعَادٍ وَثَمُودَ وَقَوْمِ إِبْرَٰهِيمَ وَأَصْحَـٰبِ مَدْيَنَ وَٱلْمُؤْتَفِكَـٰتِ ۚ أَتَتْهُمْ رُسُلُهُم بِٱلْبَيِّنَـٰتِ ۖ فَمَا كَانَ ٱللَّهُ لِيَظْلِمَهُمْ وَلَـٰكِن كَانُوٓا۟ أَنفُسَهُمْ يَظْلِمُونَ
Transliteration alam yatihim naba-u alladhīna min qablihim qawmi nūḥin waʿādin wathamūda waqawmi ib'rāhīma wa-aṣḥābi madyana wal-mu'tafikāti atathum rusuluhum bil-bayināti famā kāna l-lahu liyaẓlimahum walākin kānū anfusahum yaẓlimūna
Yoruba Ṣé ìròyìn àwọn tó ṣíwájú wọn kò tí ì dé bá wọn ni? (Ìròyìn) ìjọ (Ànábì) Nūh, ìran ‘Ād, ìran Thamūd, ìjọ (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm, àwọn ará Mọdyan àti àwọn ìlú tí A dojú rẹ̀ bolẹ̀ (ìjọ Ànábì Lūt); àwọn Òjíṣẹ́ wọn wá bá wọn pẹ̀lú àwọn ẹ̀rí tó yanjú. Nítorí náà, Allāhu kò ṣe àbòsí sí wọn, ṣùgbọ́n ẹ̀mí ara wọn ni wọ́n ṣàbòsí sí.
Verse 71
وَٱلْمُؤْمِنُونَ وَٱلْمُؤْمِنَـٰتُ بَعْضُهُمْ أَوْلِيَآءُ بَعْضٍ ۚ يَأْمُرُونَ بِٱلْمَعْرُوفِ وَيَنْهَوْنَ عَنِ ٱلْمُنكَرِ وَيُقِيمُونَ ٱلصَّلَوٰةَ وَيُؤْتُونَ ٱلزَّكَوٰةَ وَيُطِيعُونَ ٱللَّهَ وَرَسُولَهُۥٓ ۚ أُو۟لَـٰٓئِكَ سَيَرْحَمُهُمُ ٱللَّهُ ۗ إِنَّ ٱللَّهَ عَزِيزٌ حَكِيمٌ
Transliteration wal-mu'minūna wal-mu'minātu baʿḍuhum awliyāu baʿḍin yamurūna bil-maʿrūfi wayanhawna ʿani l-munkari wayuqīmūna l-ṣalata wayu'tūna l-zakata wayuṭīʿūna l-laha warasūlahu ulāika sayarḥamuhumu l-lahu inna l-laha ʿazīzun ḥakīmun
Yoruba Àwọn onígbàgbọ́ òdodo lọ́kùnrin àti àwọn onígbàgbọ́ òdodo lóbìnrin, apá kan wọn lọ̀rẹ́ alátìlẹ́yìn fún apá kan; wọ́n ń pàṣẹ ohun rere, wọ́n ń kọ ohun burúkú, wọ́n ń kírun, wọ́n ń yọ Zakāh, wọ́n sì ń tẹ̀lé ti Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀. Àwọn wọ̀nyẹn ni Allāhu yóò ṣàkẹ́. Dájúdájú Allāhu ni Alágbára, Ọlọ́gbọ́n.
Verse 72
وَعَدَ ٱللَّهُ ٱلْمُؤْمِنِينَ وَٱلْمُؤْمِنَـٰتِ جَنَّـٰتٍ تَجْرِى مِن تَحْتِهَا ٱلْأَنْهَـٰرُ خَـٰلِدِينَ فِيهَا وَمَسَـٰكِنَ طَيِّبَةً فِى جَنَّـٰتِ عَدْنٍ ۚ وَرِضْوَٰنٌ مِّنَ ٱللَّهِ أَكْبَرُ ۚ ذَٰلِكَ هُوَ ٱلْفَوْزُ ٱلْعَظِيمُ
Transliteration waʿada l-lahu l-mu'minīna wal-mu'mināti jannātin tajrī min taḥtihā l-anhāru khālidīna fīhā wamasākina ṭayyibatan fī jannāti ʿadnin wariḍ'wānun mina l-lahi akbaru dhālika huwa l-fawzu l-ʿaẓīmu
Yoruba Allāhu ṣe àdéhùn àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo lọ́kùnrin àti àwọn onígbàgbọ́ òdodo lóbìnrin, èyí tí àwọn odò ń ṣàn ní ìsàlẹ̀ rẹ̀. Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀. (Ó tún ṣe àdéhùn) àwọn ibùgbé tó dára nínú àwọn ọgbà ìdẹ̀ra gbére (fún wọn). Ìyọ́nú láti ọ̀dọ̀ Allāhu ló sì tóbi jùlọ (fún wọn). Ìyẹn, òhun ni èrèǹjẹ ńlá.
Verse 73
يَـٰٓأَيُّهَا ٱلنَّبِىُّ جَـٰهِدِ ٱلْكُفَّارَ وَٱلْمُنَـٰفِقِينَ وَٱغْلُظْ عَلَيْهِمْ ۚ وَمَأْوَىٰهُمْ جَهَنَّمُ ۖ وَبِئْسَ ٱلْمَصِيرُ
Transliteration yāayyuhā l-nabiyu jāhidi l-kufāra wal-munāfiqīna wa-ugh'luẓ ʿalayhim wamawāhum jahannamu wabi'sa l-maṣīru
Yoruba Ìwọ Ànábì, gbógun ti àwọn aláìgbàgbọ́ àti àwọn ṣọ̀bẹ-ṣèlu mùsùlùmí. Kí o sì le mọ́ wọn. Iná Jahanamọ ni ibùgbé wọn. Ìkángun náà sì burú.
Verse 74
يَحْلِفُونَ بِٱللَّهِ مَا قَالُوا۟ وَلَقَدْ قَالُوا۟ كَلِمَةَ ٱلْكُفْرِ وَكَفَرُوا۟ بَعْدَ إِسْلَـٰمِهِمْ وَهَمُّوا۟ بِمَا لَمْ يَنَالُوا۟ ۚ وَمَا نَقَمُوٓا۟ إِلَّآ أَنْ أَغْنَىٰهُمُ ٱللَّهُ وَرَسُولُهُۥ مِن فَضْلِهِۦ ۚ فَإِن يَتُوبُوا۟ يَكُ خَيْرًا لَّهُمْ ۖ وَإِن يَتَوَلَّوْا۟ يُعَذِّبْهُمُ ٱللَّهُ عَذَابًا أَلِيمًا فِى ٱلدُّنْيَا وَٱلْـَٔاخِرَةِ ۚ وَمَا لَهُمْ فِى ٱلْأَرْضِ مِن وَلِىٍّ وَلَا نَصِيرٍ
Transliteration yaḥlifūna bil-lahi mā qālū walaqad qālū kalimata l-kuf'ri wakafarū baʿda is'lāmihim wahammū bimā lam yanālū wamā naqamū illā an aghnāhumu l-lahu warasūluhu min faḍlihi fa-in yatūbū yaku khayran lahum wa-in yatawallaw yuʿadhib'humu l-lahu ʿadhāban alīman fī l-dun'yā wal-ākhirati wamā lahum fī l-arḍi min waliyyin walā naṣīrin
Yoruba Wọ́n ń fi Allāhu búra pé àwọn kò sọ̀rọ̀ (burúkú). Wọ́n sì kúkú ti sọ ọ̀rọ̀ àìgbàgbọ́, wọ́n sì ṣàì gbàgbọ́ lẹ́yìn tí wọ́n ti gba ’Islām. Wọ́n tún gbèròkérò sí n̄ǹkan tí ọwọ́ wọn kò níí bà. Wọn kò rí àlèébù kan (wọn kò sì kórira kiní kan) bí kò ṣe nítorí pé, Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀ rọ àwọn (Sọhābah) lọ́rọ̀ nínú ọlá Rẹ̀. Tí wọ́n bá ronú pìwàdà, ó máa dára fún wọn. Tí wọ́n bá sì gbúnrí (tí wọ́n kọ̀yìn si yín), Allāhu yóò jẹ wọ́n níyà ẹlẹ́ta-eléro ní ayé àti ní ọ̀run. Kò sì níí sí aláàbò àti alárànṣe kan fún wọn lórí ilẹ̀ ayé.
Verse 75
۞ وَمِنْهُم مَّنْ عَـٰهَدَ ٱللَّهَ لَئِنْ ءَاتَىٰنَا مِن فَضْلِهِۦ لَنَصَّدَّقَنَّ وَلَنَكُونَنَّ مِنَ ٱلصَّـٰلِحِينَ
Transliteration wamin'hum man ʿāhada l-laha la-in ātānā min faḍlihi lanaṣṣaddaqanna walanakūnanna mina l-ṣāliḥīna
Yoruba Ó wà nínú wọn, ẹni tó bá Allāhu ṣe àdéhùn pé: “Tí Ó bá fún wa nínú oore àjùlọ Rẹ̀, dájúdájú a óò máa tọrẹ, dájúdájú a ó sì wà nínú àwọn ẹni ire.”
Verse 76
فَلَمَّآ ءَاتَىٰهُم مِّن فَضْلِهِۦ بَخِلُوا۟ بِهِۦ وَتَوَلَّوا۟ وَّهُم مُّعْرِضُونَ
Transliteration falammā ātāhum min faḍlihi bakhilū bihi watawallaw wahum muʿ'riḍūna
Yoruba Àmọ́ nígbà tí Ó fún wọn nínú oore àjùlọ Rẹ̀, wọ́n ṣahun sí I. Wọ́n pẹ̀yìn dà, wọ́n sì ń gbúnrí (láti náwó fẹ́sìn).
Verse 77
فَأَعْقَبَهُمْ نِفَاقًا فِى قُلُوبِهِمْ إِلَىٰ يَوْمِ يَلْقَوْنَهُۥ بِمَآ أَخْلَفُوا۟ ٱللَّهَ مَا وَعَدُوهُ وَبِمَا كَانُوا۟ يَكْذِبُونَ
Transliteration fa-aʿqabahum nifāqan fī qulūbihim ilā yawmi yalqawnahu bimā akhlafū l-laha mā waʿadūhu wabimā kānū yakdhibūna
Yoruba Nítorí náà, ahun wọn mú ọ̀rọ̀ wọn kángun sí ìṣọ̀bẹ-ṣèlu nínú ọkàn wọn títí di ọjọ́ tí wọn yóò pàdé Allāhu nítorí pé wọ́n yẹ àdéhùn tí wọ́n bá Allāhu ṣe àti nítorí pé wọ́n ń parọ́.
Verse 78
أَلَمْ يَعْلَمُوٓا۟ أَنَّ ٱللَّهَ يَعْلَمُ سِرَّهُمْ وَنَجْوَىٰهُمْ وَأَنَّ ٱللَّهَ عَلَّـٰمُ ٱلْغُيُوبِ
Transliteration alam yaʿlamū anna l-laha yaʿlamu sirrahum wanajwāhum wa-anna l-laha ʿallāmu l-ghuyūbi
Yoruba Ṣé wọn kò mọ̀ pé Allāhu mọ àṣírí wọn àti ọ̀rọ̀ àtẹ̀sọ wọn, àti pé dájúdájú Allāhu ni Onímọ̀ nípa àwọn ìkọ̀kọ̀?
Verse 79
ٱلَّذِينَ يَلْمِزُونَ ٱلْمُطَّوِّعِينَ مِنَ ٱلْمُؤْمِنِينَ فِى ٱلصَّدَقَـٰتِ وَٱلَّذِينَ لَا يَجِدُونَ إِلَّا جُهْدَهُمْ فَيَسْخَرُونَ مِنْهُمْ ۙ سَخِرَ ٱللَّهُ مِنْهُمْ وَلَهُمْ عَذَابٌ أَلِيمٌ
Transliteration alladhīna yalmizūna l-muṭawiʿīna mina l-mu'minīna fī l-ṣadaqāti wa-alladhīna lā yajidūna illā juh'dahum fayaskharūna min'hum sakhira l-lahu min'hum walahum ʿadhābun alīmun
Yoruba Àwọn tó ń bú àwọn olùtọrẹ-àánú nínú àwọn onígbàgbọ́ òdodo lórí ọrẹ títa àti àwọn tí kò rí n̄ǹkan kan tayọ ìwọ̀n agbára wọn, wọ́n sì ń fi wọn ṣe yẹ̀yẹ́, Allāhu fi àwọn náà ṣe yẹ̀yẹ́. Ìyà ẹlẹ́ta-eléro sì wà fún wọn.
Verse 80
ٱسْتَغْفِرْ لَهُمْ أَوْ لَا تَسْتَغْفِرْ لَهُمْ إِن تَسْتَغْفِرْ لَهُمْ سَبْعِينَ مَرَّةً فَلَن يَغْفِرَ ٱللَّهُ لَهُمْ ۚ ذَٰلِكَ بِأَنَّهُمْ كَفَرُوا۟ بِٱللَّهِ وَرَسُولِهِۦ ۗ وَٱللَّهُ لَا يَهْدِى ٱلْقَوْمَ ٱلْفَـٰسِقِينَ
Transliteration is'taghfir lahum aw lā tastaghfir lahum in tastaghfir lahum sabʿīna marratan falan yaghfira l-lahu lahum dhālika bi-annahum kafarū bil-lahi warasūlihi wal-lahu lā yahdī l-qawma l-fāsiqīna
Yoruba Yálà o tọrọ àforíjìn fún wọ́n tàbí o ò tọrọ àforíjìn fún wọn - kódà kí o tọrọ àforíjìn fún wọn nígbà ààdọ́rin - Allāhu kò níí foríjìn wọ́n. Ìyẹn nítorí pé, dájúdájú wọ́n ṣàì gbàgbọ́ nínú Allāhu àti Òjísẹ́ Rẹ̀. Allāhu kò níí fi ọ̀nà mọ ìjọ òbìlẹ̀jẹ́.1
Verse 81
فَرِحَ ٱلْمُخَلَّفُونَ بِمَقْعَدِهِمْ خِلَـٰفَ رَسُولِ ٱللَّهِ وَكَرِهُوٓا۟ أَن يُجَـٰهِدُوا۟ بِأَمْوَٰلِهِمْ وَأَنفُسِهِمْ فِى سَبِيلِ ٱللَّهِ وَقَالُوا۟ لَا تَنفِرُوا۟ فِى ٱلْحَرِّ ۗ قُلْ نَارُ جَهَنَّمَ أَشَدُّ حَرًّا ۚ لَّوْ كَانُوا۟ يَفْقَهُونَ
Transliteration fariḥa l-mukhalafūna bimaqʿadihim khilāfa rasūli l-lahi wakarihū an yujāhidū bi-amwālihim wa-anfusihim fī sabīli l-lahi waqālū lā tanfirū fī l-ḥari qul nāru jahannama ashaddu ḥarran law kānū yafqahūna
Yoruba Àwọn olùsásẹ́yìn fún ogun ẹ̀sìn dunnú sí jíjókòó sínú ilé wọn lẹ́yìn Òjíṣẹ́ Allāhu. Wọ́n sì kórira láti fi dúkìá wọn àti ẹ̀mí wọn jagun lójú ọ̀nà (ẹ̀sìn) Allāhu. Wọ́n tún wí pé: “Ẹ má lọ jagun nínú ooru gbígbóná.” Sọ pé: “Iná Jahanamọ le jùlọ ní gbígbóná, tí ó bá jẹ́ pé wọ́n gbọ́ àgbọ́yé ọ̀rọ̀.”
Verse 82
فَلْيَضْحَكُوا۟ قَلِيلًا وَلْيَبْكُوا۟ كَثِيرًا جَزَآءًۢ بِمَا كَانُوا۟ يَكْسِبُونَ
Transliteration falyaḍḥakū qalīlan walyabkū kathīran jazāan bimā kānū yaksibūna
Yoruba Nítorí náà, kí wọ́n rẹ́rìn-ín díẹ̀, kí wọ́n sì sunkún púpọ̀; (ó jẹ́) ẹ̀san (fún) ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́.
Verse 83
فَإِن رَّجَعَكَ ٱللَّهُ إِلَىٰ طَآئِفَةٍ مِّنْهُمْ فَٱسْتَـْٔذَنُوكَ لِلْخُرُوجِ فَقُل لَّن تَخْرُجُوا۟ مَعِىَ أَبَدًا وَلَن تُقَـٰتِلُوا۟ مَعِىَ عَدُوًّا ۖ إِنَّكُمْ رَضِيتُم بِٱلْقُعُودِ أَوَّلَ مَرَّةٍ فَٱقْعُدُوا۟ مَعَ ٱلْخَـٰلِفِينَ
Transliteration fa-in rajaʿaka l-lahu ilā ṭāifatin min'hum fa-is'tadhanūka lil'khurūji faqul lan takhrujū maʿiya abadan walan tuqātilū maʿiya ʿaduwwan innakum raḍītum bil-quʿūdi awwala marratin fa-uq'ʿudū maʿa l-khālifīna
Yoruba Tí Allāhu bá mú ọ délé bá igun kan nínú wọn, tí wọ́n bá wá ń gbàṣẹ lọ́dọ̀ rẹ fún jíjáde fún ogun ẹ̀sìn, sọ nígbà náà pé: “Ẹ̀yin kò lè jáde fún ogun ẹ̀sìn mọ́ pẹ̀lú mi. Ẹ̀yin kò sì lè ja ọ̀tá kan lógun mọ́ pẹ̀lú mi, nítorí pé ẹ ti yọ́nú sí ìjókòó sílé ní ìgbà àkọ́kọ́. Nítorí náà, ẹ jókòó sílé ti àwọn olùsásẹ́yìn fún ogun ẹ̀sìn.”
Verse 84
وَلَا تُصَلِّ عَلَىٰٓ أَحَدٍ مِّنْهُم مَّاتَ أَبَدًا وَلَا تَقُمْ عَلَىٰ قَبْرِهِۦٓ ۖ إِنَّهُمْ كَفَرُوا۟ بِٱللَّهِ وَرَسُولِهِۦ وَمَاتُوا۟ وَهُمْ فَـٰسِقُونَ
Transliteration walā tuṣalli ʿalā aḥadin min'hum māta abadan walā taqum ʿalā qabrihi innahum kafarū bil-lahi warasūlihi wamātū wahum fāsiqūna
Yoruba Láéláé, o ò gbọdọ̀ kírun sí ẹnì kan kan lára nínú wọn, tí ó bá kú, o ò sì gbọdọ̀ dúró níbi sàréè rẹ̀, nítorí pé wọ́n ṣàì gbàgbọ́ nínú Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀. Wọ́n sì kú nígbà tí wọ́n wà nípò òbìlẹ̀jẹ́.
Verse 85
وَلَا تُعْجِبْكَ أَمْوَٰلُهُمْ وَأَوْلَـٰدُهُمْ ۚ إِنَّمَا يُرِيدُ ٱللَّهُ أَن يُعَذِّبَهُم بِهَا فِى ٱلدُّنْيَا وَتَزْهَقَ أَنفُسُهُمْ وَهُمْ كَـٰفِرُونَ
Transliteration walā tuʿ'jib'ka amwāluhum wa-awlāduhum innamā yurīdu l-lahu an yuʿadhibahum bihā fī l-dun'yā watazhaqa anfusuhum wahum kāfirūna
Yoruba Má ṣe jẹ́ kí àwọn dúkìá wọn àti àwọn ọmọ wọn jọ ọ́ lójú; Allāhu kàn fẹ́ fi jẹ wọ́n níyà nínú ìṣẹ̀mí ayé (yìí) ni. (Ó sì fẹ́ kí) ẹ̀mí bọ́ lára wọn, nígbà tí wọ́n bá wà nípò aláìgbàgbọ́.
Verse 86
وَإِذَآ أُنزِلَتْ سُورَةٌ أَنْ ءَامِنُوا۟ بِٱللَّهِ وَجَـٰهِدُوا۟ مَعَ رَسُولِهِ ٱسْتَـْٔذَنَكَ أُو۟لُوا۟ ٱلطَّوْلِ مِنْهُمْ وَقَالُوا۟ ذَرْنَا نَكُن مَّعَ ٱلْقَـٰعِدِينَ
Transliteration wa-idhā unzilat sūratun an āminū bil-lahi wajāhidū maʿa rasūlihi is'tadhanaka ulū l-ṭawli min'hum waqālū dharnā nakun maʿa l-qāʿidīna
Yoruba Nígbà tí A bá sọ sūrah kan kalẹ̀ pé kí wọ́n gbàgbọ́ nínú Allāhu, kí wọ́n sí jagun pẹ̀lú Òjíṣẹ́ Rẹ̀, (nígbà náà ni) àwọn ọlọ́rọ̀ nínú wọn yóò máa tọrọ ìyọ̀ǹda lọ́dọ̀ rẹ, wọ́n á sì wí pé: “Fi wá sílẹ̀ kí á wà pẹ̀lú àwọn olùjókòó sílé.”
Verse 87
رَضُوا۟ بِأَن يَكُونُوا۟ مَعَ ٱلْخَوَالِفِ وَطُبِعَ عَلَىٰ قُلُوبِهِمْ فَهُمْ لَا يَفْقَهُونَ
Transliteration raḍū bi-an yakūnū maʿa l-khawālifi waṭubiʿa ʿalā qulūbihim fahum lā yafqahūna
Yoruba Wọ́n yọ́nú sí kí wọ́n máa wà pẹ̀lú àwọn olùsásẹ́yìn fún ogun ẹ̀sìn. Wọ́n ti fi èdídí dí ọkàn wọn pa; nítorí náà, wọn kò níí gbọ́ àgbọ́yé.
Verse 88
لَـٰكِنِ ٱلرَّسُولُ وَٱلَّذِينَ ءَامَنُوا۟ مَعَهُۥ جَـٰهَدُوا۟ بِأَمْوَٰلِهِمْ وَأَنفُسِهِمْ ۚ وَأُو۟لَـٰٓئِكَ لَهُمُ ٱلْخَيْرَٰتُ ۖ وَأُو۟لَـٰٓئِكَ هُمُ ٱلْمُفْلِحُونَ
Transliteration lākini l-rasūlu wa-alladhīna āmanū maʿahu jāhadū bi-amwālihim wa-anfusihim wa-ulāika lahumu l-khayrātu wa-ulāika humu l-muf'liḥūna
Yoruba Ṣùgbọ́n Òjíṣẹ́ àti àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo pẹ̀lú rẹ̀, wọ́n fi dúkìá wọn àti ẹ̀mí wọn jagun ẹ̀sìn. Àwọn wọ̀nyẹn, àwọn oore ń bẹ fún wọn. Àwọn wọ̀nyẹn, àwọn sì ni olùjèrè.
Verse 89
أَعَدَّ ٱللَّهُ لَهُمْ جَنَّـٰتٍ تَجْرِى مِن تَحْتِهَا ٱلْأَنْهَـٰرُ خَـٰلِدِينَ فِيهَا ۚ ذَٰلِكَ ٱلْفَوْزُ ٱلْعَظِيمُ
Transliteration aʿadda l-lahu lahum jannātin tajrī min taḥtihā l-anhāru khālidīna fīhā dhālika l-fawzu l-ʿaẓīmu
Yoruba Allāhu ti pèsè sílẹ̀ dè wọ́n àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra kan tí odò ń ṣàn ní ìsàlẹ̀ rẹ̀. Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀. Ìyẹn ni èrèǹjẹ ńlá.
Verse 90
وَجَآءَ ٱلْمُعَذِّرُونَ مِنَ ٱلْأَعْرَابِ لِيُؤْذَنَ لَهُمْ وَقَعَدَ ٱلَّذِينَ كَذَبُوا۟ ٱللَّهَ وَرَسُولَهُۥ ۚ سَيُصِيبُ ٱلَّذِينَ كَفَرُوا۟ مِنْهُمْ عَذَابٌ أَلِيمٌ
Transliteration wajāa l-muʿadhirūna mina l-aʿrābi liyu'dhana lahum waqaʿada alladhīna kadhabū l-laha warasūlahu sayuṣību alladhīna kafarū min'hum ʿadhābun alīmun
Yoruba Àwọn aláwàáwí nínú àwọn Lárúbáwá oko wá (bá ọ) nítorí kí wọ́n lè yọ̀ǹda (ìjókòó sílé) fún wọn. Àwọn tó sì pe ọ̀rọ̀ Allāhu àti ọ̀rọ̀ Òjíṣẹ́ nírọ́ náà jókòó sílé. Ọwọ́ ìyà ẹlẹ́ta-eléro máa ba àwọn aláìgbàgbọ́ nínú wọn.
Verse 91
لَّيْسَ عَلَى ٱلضُّعَفَآءِ وَلَا عَلَى ٱلْمَرْضَىٰ وَلَا عَلَى ٱلَّذِينَ لَا يَجِدُونَ مَا يُنفِقُونَ حَرَجٌ إِذَا نَصَحُوا۟ لِلَّهِ وَرَسُولِهِۦ ۚ مَا عَلَى ٱلْمُحْسِنِينَ مِن سَبِيلٍ ۚ وَٱللَّهُ غَفُورٌ رَّحِيمٌ
Transliteration laysa ʿalā l-ḍuʿafāi walā ʿalā l-marḍā walā ʿalā alladhīna lā yajidūna mā yunfiqūna ḥarajun idhā naṣaḥū lillahi warasūlihi mā ʿalā l-muḥ'sinīna min sabīlin wal-lahu ghafūrun raḥīmun
Yoruba Kò sí ẹ̀ṣẹ̀ fún àwọn aláìlágbára, àwọn aláìsàn àti àwọn tí kò rí ohun tí wọn máa ná ní owó (láti fi jagun ẹ̀sìn) nígbà tí wọ́n bá ti ní òtítọ́-inú sí Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀. Kò sí ọ̀nà kan (tó máa já sí ìyà) fún àwọn olùṣe-rere sẹ́. Allāhu sì ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.
Verse 92
وَلَا عَلَى ٱلَّذِينَ إِذَا مَآ أَتَوْكَ لِتَحْمِلَهُمْ قُلْتَ لَآ أَجِدُ مَآ أَحْمِلُكُمْ عَلَيْهِ تَوَلَّوا۟ وَّأَعْيُنُهُمْ تَفِيضُ مِنَ ٱلدَّمْعِ حَزَنًا أَلَّا يَجِدُوا۟ مَا يُنفِقُونَ
Transliteration walā ʿalā alladhīna idhā mā atawka litaḥmilahum qul'ta lā ajidu mā aḥmilukum ʿalayhi tawallaw wa-aʿyunuhum tafīḍu mina l-damʿi ḥazanan allā yajidū mā yunfiqūna
Yoruba Kò tún sí ẹ̀ṣẹ̀ fún àwọn tí (ó jẹ́ pé) nígbà tí wọ́n bá wá bá ọ pé kí o fún àwọn ní n̄ǹkan tí àwọn yóò gùn (lọ sójú ogun), tí o sì sọ pé, “Èmi kò rí n̄ǹkan tí mo lè fún yín gùn (lọ sójú ogun), wọ́n máa padà pẹ̀lú ojú wọn tí yóò máa damije ní ti ìbànújẹ́ pé wọn kò rí n̄ǹkan tí wọ́n máa ná (lọ sójú ogun ẹ̀sìn).
Verse 93
۞ إِنَّمَا ٱلسَّبِيلُ عَلَى ٱلَّذِينَ يَسْتَـْٔذِنُونَكَ وَهُمْ أَغْنِيَآءُ ۚ رَضُوا۟ بِأَن يَكُونُوا۟ مَعَ ٱلْخَوَالِفِ وَطَبَعَ ٱللَّهُ عَلَىٰ قُلُوبِهِمْ فَهُمْ لَا يَعْلَمُونَ
Transliteration innamā l-sabīlu ʿalā alladhīna yastadhinūnaka wahum aghniyāu raḍū bi-an yakūnū maʿa l-khawālifi waṭabaʿa l-lahu ʿalā qulūbihim fahum lā yaʿlamūna
Yoruba Àwọn tí ọ̀nà kan (tó máa já sí ìyà) wà fún ni àwọn tó ń tọrọ ìyọ̀ǹda lọ́dọ̀ rẹ (láti jókòó sílé, tí) wọ́n sì jẹ́ ọlọ́rọ̀, tí wọ́n yọ́nú sí kí wọ́n wà pẹ̀lú àwọn olùsásẹ́yìn fún ogun ẹ̀sìn. Allāhu ti fi èdídí dí ọkàn wọn pa; nítorí náà, wọn kò sì mọ̀.
Verse 94
يَعْتَذِرُونَ إِلَيْكُمْ إِذَا رَجَعْتُمْ إِلَيْهِمْ ۚ قُل لَّا تَعْتَذِرُوا۟ لَن نُّؤْمِنَ لَكُمْ قَدْ نَبَّأَنَا ٱللَّهُ مِنْ أَخْبَارِكُمْ ۚ وَسَيَرَى ٱللَّهُ عَمَلَكُمْ وَرَسُولُهُۥ ثُمَّ تُرَدُّونَ إِلَىٰ عَـٰلِمِ ٱلْغَيْبِ وَٱلشَّهَـٰدَةِ فَيُنَبِّئُكُم بِمَا كُنتُمْ تَعْمَلُونَ
Transliteration yaʿtadhirūna ilaykum idhā rajaʿtum ilayhim qul lā taʿtadhirū lan nu'mina lakum qad nabba-anā l-lahu min akhbārikum wasayarā l-lahu ʿamalakum warasūluhu thumma turaddūna ilā ʿālimi l-ghaybi wal-shahādati fayunabbi-ukum bimā kuntum taʿmalūna
Yoruba Wọ́n yóò mú àwáwí wá fún yín nígbà tí ẹ bá dé bá wọn nílé. Sọ pé: "Ẹ má ṣe mú àwáwí wá; a ò níí gbà yín gbọ́. Allāhu kúkú ti sọ àwọn ọ̀rọ̀ yín fún wa. Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀ yó sì rí iṣẹ́ (ọwọ́) yín.Lẹ́yìn náà, A óò da yín padà sí ọ̀dọ̀ Onímọ̀-ìkọ̀kọ̀ àti gban̄gba. Nígbà náà, Ó máa fún yín ní ìró ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.
Verse 95
سَيَحْلِفُونَ بِٱللَّهِ لَكُمْ إِذَا ٱنقَلَبْتُمْ إِلَيْهِمْ لِتُعْرِضُوا۟ عَنْهُمْ ۖ فَأَعْرِضُوا۟ عَنْهُمْ ۖ إِنَّهُمْ رِجْسٌ ۖ وَمَأْوَىٰهُمْ جَهَنَّمُ جَزَآءًۢ بِمَا كَانُوا۟ يَكْسِبُونَ
Transliteration sayaḥlifūna bil-lahi lakum idhā inqalabtum ilayhim lituʿ'riḍū ʿanhum fa-aʿriḍū ʿanhum innahum rij'sun wamawāhum jahannamu jazāan bimā kānū yaksibūna
Yoruba Wọ́n yóò máa fi Allāhu búra fún yín nígbà tí ẹ bá dé bá wọn, nítorí kí ẹ lè pa wọ́n tì. Nítorí náà, ẹ pa wọ́n tì; dájúdájú ẹ̀gbin ni wọ́n. Iná Jahanamọ sì ni ibùgbé wọn. (Ó jẹ́) ẹ̀san nítorí ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́.
Verse 96
يَحْلِفُونَ لَكُمْ لِتَرْضَوْا۟ عَنْهُمْ ۖ فَإِن تَرْضَوْا۟ عَنْهُمْ فَإِنَّ ٱللَّهَ لَا يَرْضَىٰ عَنِ ٱلْقَوْمِ ٱلْفَـٰسِقِينَ
Transliteration yaḥlifūna lakum litarḍaw ʿanhum fa-in tarḍaw ʿanhum fa-inna l-laha lā yarḍā ʿani l-qawmi l-fāsiqīna
Yoruba Wọ́n yóò máa búra fún yín nítorí kí ẹ lè yọ́nú sí wọn. Tí ẹ bá yọ́nú sí wọn, dájúdájú Allāhu kò níí yọ́nú sí ìjọ òbìlẹ̀jẹ́.
Verse 97
ٱلْأَعْرَابُ أَشَدُّ كُفْرًا وَنِفَاقًا وَأَجْدَرُ أَلَّا يَعْلَمُوا۟ حُدُودَ مَآ أَنزَلَ ٱللَّهُ عَلَىٰ رَسُولِهِۦ ۗ وَٱللَّهُ عَلِيمٌ حَكِيمٌ
Transliteration al-aʿrābu ashaddu kuf'ran wanifāqan wa-ajdaru allā yaʿlamū ḥudūda mā anzala l-lahu ʿalā rasūlihi wal-lahu ʿalīmun ḥakīmun
Yoruba Àwọn Lárúbáwá oko le nínú àìgbàgbọ́ àti ìṣọ̀bẹ-ṣèlu. Ó sì súnmọ́ jùlọ pé wọ́n kò mọ àwọn ẹnu-ààlà ohun tí Allāhu sọ̀kalẹ̀ fún Òjíṣẹ́ Rẹ̀. Allāhu sì ni Onímọ̀, Ọlọ́gbọ́n.
Verse 98
وَمِنَ ٱلْأَعْرَابِ مَن يَتَّخِذُ مَا يُنفِقُ مَغْرَمًا وَيَتَرَبَّصُ بِكُمُ ٱلدَّوَآئِرَ ۚ عَلَيْهِمْ دَآئِرَةُ ٱلسَّوْءِ ۗ وَٱللَّهُ سَمِيعٌ عَلِيمٌ
Transliteration wamina l-aʿrābi man yattakhidhu mā yunfiqu maghraman wayatarabbaṣu bikumu l-dawāira ʿalayhim dāiratu l-sawi wal-lahu samīʿun ʿalīmun
Yoruba Àti pé ó wà nínú àwọn Lárúbáwá oko ẹni tí ó ka ìnáwó tó ń ná (fún ẹ̀sìn) sí owó ọ̀ràn. Ó sì ń retí àpadàsí aburú fún yín. Àwọn sì ni àpadàsí aburú yóò dé bá. Allāhu sì ni Olùgbọ́, Onímọ̀.
Verse 99
وَمِنَ ٱلْأَعْرَابِ مَن يُؤْمِنُ بِٱللَّهِ وَٱلْيَوْمِ ٱلْـَٔاخِرِ وَيَتَّخِذُ مَا يُنفِقُ قُرُبَـٰتٍ عِندَ ٱللَّهِ وَصَلَوَٰتِ ٱلرَّسُولِ ۚ أَلَآ إِنَّهَا قُرْبَةٌ لَّهُمْ ۚ سَيُدْخِلُهُمُ ٱللَّهُ فِى رَحْمَتِهِۦٓ ۗ إِنَّ ٱللَّهَ غَفُورٌ رَّحِيمٌ
Transliteration wamina l-aʿrābi man yu'minu bil-lahi wal-yawmi l-ākhiri wayattakhidhu mā yunfiqu qurubātin ʿinda l-lahi waṣalawāti l-rasūli alā innahā qur'batun lahum sayud'khiluhumu l-lahu fī raḥmatihi inna l-laha ghafūrun raḥīmun
Yoruba Ó tún wà nínú àwọn Lárúbáwá oko, ẹni tí ó gbàgbọ́ nínú Allāhu àti Ọjọ́ Ìkẹ́yìn, tí ó sì sọ ìnáwó tó ń ná (fún ẹ̀sìn) di ohun tí ó máa mú wọn súnmọ́ Allāhu àti ohun tí ó máa mú wọn gba àdùá lọ́dọ̀ Òjíṣẹ́. Kíyè sí i, dájúdájú ó máa mú wọn súnmọ́ Allāhu. Allāhu yó sì fi wọ́n sínú ìkẹ́ Rẹ̀. Dájúdájú Allāhu ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.
Verse 100
وَٱلسَّـٰبِقُونَ ٱلْأَوَّلُونَ مِنَ ٱلْمُهَـٰجِرِينَ وَٱلْأَنصَارِ وَٱلَّذِينَ ٱتَّبَعُوهُم بِإِحْسَـٰنٍ رَّضِىَ ٱللَّهُ عَنْهُمْ وَرَضُوا۟ عَنْهُ وَأَعَدَّ لَهُمْ جَنَّـٰتٍ تَجْرِى تَحْتَهَا ٱلْأَنْهَـٰرُ خَـٰلِدِينَ فِيهَآ أَبَدًا ۚ ذَٰلِكَ ٱلْفَوْزُ ٱلْعَظِيمُ
Transliteration wal-sābiqūna l-awalūna mina l-muhājirīna wal-anṣāri wa-alladhīna ittabaʿūhum bi-iḥ'sānin raḍiya l-lahu ʿanhum waraḍū ʿanhu wa-aʿadda lahum jannātin tajrī taḥtahā l-anhāru khālidīna fīhā abadan dhālika l-fawzu l-ʿaẓīmu
Yoruba Àwọn aṣíwájú, àwọn ẹni àkọ́kọ́ nínú àwọn Muhājirūn àti àwọn ’Ansọ̄r àti àwọn tó fi dáadáa tẹ̀lé wọn, Allāhu yọ́nú sí wọn. Wọ́n sì yọ́nú sí (ohun tí Allāhu fún wọn). Ó tún pa lésè sílẹ̀ dè wọ́n àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra tí odò ń ṣàn ní ìsàlẹ̀ rẹ̀. Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ títí láéláé. Ìyẹn ni èrèǹjẹ ńlá.
Verse 101
وَمِمَّنْ حَوْلَكُم مِّنَ ٱلْأَعْرَابِ مُنَـٰفِقُونَ ۖ وَمِنْ أَهْلِ ٱلْمَدِينَةِ ۖ مَرَدُوا۟ عَلَى ٱلنِّفَاقِ لَا تَعْلَمُهُمْ ۖ نَحْنُ نَعْلَمُهُمْ ۚ سَنُعَذِّبُهُم مَّرَّتَيْنِ ثُمَّ يُرَدُّونَ إِلَىٰ عَذَابٍ عَظِيمٍ
Transliteration wamimman ḥawlakum mina l-aʿrābi munāfiqūna wamin ahli l-madīnati maradū ʿalā l-nifāqi lā taʿlamuhum naḥnu naʿlamuhum sanuʿadhibuhum marratayni thumma yuraddūna ilā ʿadhābin ʿaẓīmin
Yoruba Àwọn ṣọ̀bẹ-ṣèlu mùsùlùmí kan ń bẹ nínú àwọn tí ó wà ní àyíká yín nínú àwọn Lárúbáwá oko àti nínú àwọn ará ìlú Mọdīnah, tí wọ́n won̄koko mọ́ ìṣọ̀bẹ-ṣèlú. Ìwọ kò mọ̀ wọ́n, Àwa l’A mọ̀ wọ́n. A óò jẹ wọ́n níyà ní ẹ̀ẹ̀ mejì.Lẹ́yìn náà, A óò dá wọn padà sínú ìyà ńlá.
Verse 102
وَءَاخَرُونَ ٱعْتَرَفُوا۟ بِذُنُوبِهِمْ خَلَطُوا۟ عَمَلًا صَـٰلِحًا وَءَاخَرَ سَيِّئًا عَسَى ٱللَّهُ أَن يَتُوبَ عَلَيْهِمْ ۚ إِنَّ ٱللَّهَ غَفُورٌ رَّحِيمٌ
Transliteration waākharūna iʿ'tarafū bidhunūbihim khalaṭū ʿamalan ṣāliḥan waākhara sayyi-an ʿasā l-lahu an yatūba ʿalayhim inna l-laha ghafūrun raḥīmun
Yoruba Àwọn mìíràn jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Wọ́n da iṣẹ́ rere pọ̀ mọ́ iṣẹ́ mìíràn tó burú. Bóyá Allāhu yóò gba ìronúpìwàdà wọn. Dájúdájú Allāhu ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.
Verse 103
خُذْ مِنْ أَمْوَٰلِهِمْ صَدَقَةً تُطَهِّرُهُمْ وَتُزَكِّيهِم بِهَا وَصَلِّ عَلَيْهِمْ ۖ إِنَّ صَلَوٰتَكَ سَكَنٌ لَّهُمْ ۗ وَٱللَّهُ سَمِيعٌ عَلِيمٌ
Transliteration khudh min amwālihim ṣadaqatan tuṭahhiruhum watuzakkīhim bihā waṣalli ʿalayhim inna ṣalataka sakanun lahum wal-lahu samīʿun ʿalīmun
Yoruba Gba ọrẹ (Zakāh) nínú dúkìá wọn, kí o fi sọ wọ́n di ẹni mímọ́, kí o sì fi ṣe àfọ̀mọ́ fún wọn. Ṣe àdúà fún wọn. Dájúdájú àdúà rẹ ni ìfàyàbalẹ̀ fún wọn. Allāhu sì ni Olùgbọ́, Onímọ̀.1
Verse 104
أَلَمْ يَعْلَمُوٓا۟ أَنَّ ٱللَّهَ هُوَ يَقْبَلُ ٱلتَّوْبَةَ عَنْ عِبَادِهِۦ وَيَأْخُذُ ٱلصَّدَقَـٰتِ وَأَنَّ ٱللَّهَ هُوَ ٱلتَّوَّابُ ٱلرَّحِيمُ
Transliteration alam yaʿlamū anna l-laha huwa yaqbalu l-tawbata ʿan ʿibādihi wayakhudhu l-ṣadaqāti wa-anna l-laha huwa l-tawābu l-raḥīmu
Yoruba Ṣé wọn kò mọ̀ pé dájúdájú Allāhu Òun l’Ó ń gba ìronúpìwàdà lọ́wọ́ àwọn ẹrúsìn Rẹ̀, Ó sì ń gba àwọn ọrẹ, àti pé dájúdájú Allāhu, Òun ni Olùgba-ìronúpìwàdà, Àṣàkẹ́-ọ̀run?
Verse 105
وَقُلِ ٱعْمَلُوا۟ فَسَيَرَى ٱللَّهُ عَمَلَكُمْ وَرَسُولُهُۥ وَٱلْمُؤْمِنُونَ ۖ وَسَتُرَدُّونَ إِلَىٰ عَـٰلِمِ ٱلْغَيْبِ وَٱلشَّهَـٰدَةِ فَيُنَبِّئُكُم بِمَا كُنتُمْ تَعْمَلُونَ
Transliteration waquli iʿ'malū fasayarā l-lahu ʿamalakum warasūluhu wal-mu'minūna wasaturaddūna ilā ʿālimi l-ghaybi wal-shahādati fayunabbi-ukum bimā kuntum taʿmalūna
Yoruba Sọ pé: “Ẹ ṣiṣẹ́. Allāhu á rí iṣẹ́ yín. Òjíṣẹ́ Rẹ̀ àti àwọn onígbàgbọ́ òdodo náà (máa rí i).Wọ́n sì máa da yín padà sọ́dọ̀ Onímọ̀-ìkọ̀kọ̀-àti-gban̄gba. Ó sì máa fún yín ní ìró ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.”
Verse 106
وَءَاخَرُونَ مُرْجَوْنَ لِأَمْرِ ٱللَّهِ إِمَّا يُعَذِّبُهُمْ وَإِمَّا يَتُوبُ عَلَيْهِمْ ۗ وَٱللَّهُ عَلِيمٌ حَكِيمٌ
Transliteration waākharūna mur'jawna li-amri l-lahi immā yuʿadhibuhum wa-immā yatūbu ʿalayhim wal-lahu ʿalīmun ḥakīmun
Yoruba Wọ́n so ọ̀rọ̀ àwọn yòókù rọ̀ ná títí àṣẹ Allāhu máa fi dé; yálà kí Ó jẹ wọ́n níyà tàbí kí Ó gba ìronúpìwàdà wọn.Allāhu sì ni Onímọ̀, Ọlọ́gbọ́n. 2
Verse 107
وَٱلَّذِينَ ٱتَّخَذُوا۟ مَسْجِدًا ضِرَارًا وَكُفْرًا وَتَفْرِيقًۢا بَيْنَ ٱلْمُؤْمِنِينَ وَإِرْصَادًا لِّمَنْ حَارَبَ ٱللَّهَ وَرَسُولَهُۥ مِن قَبْلُ ۚ وَلَيَحْلِفُنَّ إِنْ أَرَدْنَآ إِلَّا ٱلْحُسْنَىٰ ۖ وَٱللَّهُ يَشْهَدُ إِنَّهُمْ لَكَـٰذِبُونَ
Transliteration wa-alladhīna ittakhadhū masjidan ḍirāran wakuf'ran watafrīqan bayna l-mu'minīna wa-ir'ṣādan liman ḥāraba l-laha warasūlahu min qablu walayaḥlifunna in aradnā illā l-ḥus'nā wal-lahu yashhadu innahum lakādhibūna
Yoruba Àwọn tó kọ́ mọ́sálásí láti fi dá ìnira àti àìgbàgbọ́ sílẹ̀ àti láti fi ṣe òpínyà láààrin àwọn onígbàgbọ́ òdodo àti láti fi ṣe ibùlúgọ fún àwọn tó gbógun ti Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀ ní ìṣáájú - dájúdájú wọ́n ń búra pé “A ò gbèrò kiní kan bí kò ṣe ohun rere.” - Allāhu sì ń jẹ́rìí pé dájúdájú òpùrọ́ ni wọ́n.
Verse 108
لَا تَقُمْ فِيهِ أَبَدًا ۚ لَّمَسْجِدٌ أُسِّسَ عَلَى ٱلتَّقْوَىٰ مِنْ أَوَّلِ يَوْمٍ أَحَقُّ أَن تَقُومَ فِيهِ ۚ فِيهِ رِجَالٌ يُحِبُّونَ أَن يَتَطَهَّرُوا۟ ۚ وَٱللَّهُ يُحِبُّ ٱلْمُطَّهِّرِينَ
Transliteration lā taqum fīhi abadan lamasjidun ussisa ʿalā l-taqwā min awwali yawmin aḥaqqu an taqūma fīhi fīhi rijālun yuḥibbūna an yataṭahharū wal-lahu yuḥibbu l-muṭahirīna
Yoruba Má ṣe dúró (kírun) nínú rẹ̀ láéláé.Dájúdájú mọ́sálásí tí wọ́n bá fi ìpìlẹ̀ rẹ̀ lélẹ̀ lórí ìbẹ̀rù Allāhu láti ọjọ́ àkọ́kọ́ lo lẹ́tọ̀ọ́ jùlọ pé kí o dúró (kírun) nínú rẹ̀. Àwọn ènìyàn tó nífẹ̀ẹ́ láti máa ṣe ìmọ́ra wà nínú rẹ̀. Allāhu sì fẹ́ràn àwọn olùṣèmọ́ra.
Verse 109
أَفَمَنْ أَسَّسَ بُنْيَـٰنَهُۥ عَلَىٰ تَقْوَىٰ مِنَ ٱللَّهِ وَرِضْوَٰنٍ خَيْرٌ أَم مَّنْ أَسَّسَ بُنْيَـٰنَهُۥ عَلَىٰ شَفَا جُرُفٍ هَارٍ فَٱنْهَارَ بِهِۦ فِى نَارِ جَهَنَّمَ ۗ وَٱللَّهُ لَا يَهْدِى ٱلْقَوْمَ ٱلظَّـٰلِمِينَ
Transliteration afaman assasa bun'yānahu ʿalā taqwā mina l-lahi wariḍ'wānin khayrun am man assasa bun'yānahu ʿalā shafā jurufin hārin fa-in'hāra bihi fī nāri jahannama wal-lahu lā yahdī l-qawma l-ẓālimīna
Yoruba Ǹjẹ́ ẹni tí ó fi ìpìlẹ̀ ilé mímọ tirẹ̀ lélẹ̀ lórí ìbẹ̀rù Allāhu àti ìyọ́nú (Rẹ̀) ló lóore jùlọ ni tàbí ẹni tí ó fi ìpìlẹ̀ ilé mímọ tirẹ̀ lélẹ̀ ní ẹ̀gbẹ́ kan létí ọ̀gbun tó máa yẹ̀ lulẹ̀, tí ó sì máa yẹ̀ ẹ́ lẹ́sẹ̀ sínú iná Jahanamọ? Allāhu kò níí fi ọ̀nà mọ ìjọ alábòsí.
Verse 110
لَا يَزَالُ بُنْيَـٰنُهُمُ ٱلَّذِى بَنَوْا۟ رِيبَةً فِى قُلُوبِهِمْ إِلَّآ أَن تَقَطَّعَ قُلُوبُهُمْ ۗ وَٱللَّهُ عَلِيمٌ حَكِيمٌ
Transliteration lā yazālu bun'yānuhumu alladhī banaw rībatan fī qulūbihim illā an taqaṭṭaʿa qulūbuhum wal-lahu ʿalīmun ḥakīmun
Yoruba Ilé wọn tí wọ́n mọ kalẹ̀ kò níí yé kó iyèméjì sínú ọkàn wọn títí ọkàn wọn yóò fi já kélekèle. Allāhu sì ni Onímọ̀, Ọlọ́gbọ́n.
Verse 111
۞ إِنَّ ٱللَّهَ ٱشْتَرَىٰ مِنَ ٱلْمُؤْمِنِينَ أَنفُسَهُمْ وَأَمْوَٰلَهُم بِأَنَّ لَهُمُ ٱلْجَنَّةَ ۚ يُقَـٰتِلُونَ فِى سَبِيلِ ٱللَّهِ فَيَقْتُلُونَ وَيُقْتَلُونَ ۖ وَعْدًا عَلَيْهِ حَقًّا فِى ٱلتَّوْرَىٰةِ وَٱلْإِنجِيلِ وَٱلْقُرْءَانِ ۚ وَمَنْ أَوْفَىٰ بِعَهْدِهِۦ مِنَ ٱللَّهِ ۚ فَٱسْتَبْشِرُوا۟ بِبَيْعِكُمُ ٱلَّذِى بَايَعْتُم بِهِۦ ۚ وَذَٰلِكَ هُوَ ٱلْفَوْزُ ٱلْعَظِيمُ
Transliteration inna l-laha ish'tarā mina l-mu'minīna anfusahum wa-amwālahum bi-anna lahumu l-janata yuqātilūna fī sabīli l-lahi fayaqtulūna wayuq'talūna waʿdan ʿalayhi ḥaqqan fī l-tawrāti wal-injīli wal-qur'āni waman awfā biʿahdihi mina l-lahi fa-is'tabshirū bibayʿikumu alladhī bāyaʿtum bihi wadhālika huwa l-fawzu l-ʿaẓīmu
Yoruba Dájúdájú Allāhu ra ẹ̀mí àwọn onígbàgbọ́ òdodo àti dúkìá wọn nítorí pé dájúdájú tiwọn ni Ọgbà Ìdẹ̀ra. Wọ́n ń jagun lójú ọ̀nà (ẹ̀sìn) Allāhu; wọ́n ń pa ọ̀tá ẹ̀sìn, wọ́n sì ń pa àwọn náà. (Ó jẹ́) àdéhùn òdodo lọ́dọ̀ Allāhu nínú at-Taorāh, al-’Injīl àti al-Ƙur’ān. Ta sì ni ó lè mú àdéhùn rẹ̀ ṣẹ ju Allāhu? Nítorí náà, ẹ dunnú sí òkòwò yín tí ẹ (fi ẹ̀mí àti dúkìá yin) ṣe. Ìyẹn, òhun sì ni èrèǹjẹ ńlá.
Verse 112
ٱلتَّـٰٓئِبُونَ ٱلْعَـٰبِدُونَ ٱلْحَـٰمِدُونَ ٱلسَّـٰٓئِحُونَ ٱلرَّٰكِعُونَ ٱلسَّـٰجِدُونَ ٱلْـَٔامِرُونَ بِٱلْمَعْرُوفِ وَٱلنَّاهُونَ عَنِ ٱلْمُنكَرِ وَٱلْحَـٰفِظُونَ لِحُدُودِ ٱللَّهِ ۗ وَبَشِّرِ ٱلْمُؤْمِنِينَ
Transliteration al-tāibūna l-ʿābidūna l-ḥāmidūna l-sāiḥūna l-rākiʿūna l-sājidūna l-āmirūna bil-maʿrūfi wal-nāhūna ʿani l-munkari wal-ḥāfiẓūna liḥudūdi l-lahi wabashiri l-mu'minīna
Yoruba Àwọn olùronúpìwàdà, àwọn olùjọ́sìn (fún Allāhu), àwọn olùdúpẹ́ (fún Allāhu), àwọn aláààwẹ̀, àwọn olùdáwọ́tẹ-orúnkún (lórí ìrun), àwọn olùforíkanlẹ̀ (fún Allāhu), àwọn olùpàṣẹ-ohun rere, àwọn olùkọ-ohun burúkú àti àwọn olùṣọ́-ẹnu-ààlà tí Allāhu gbékalẹ̀, fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo (wọ̀nyí) ní ìró ìdùnnú (Ọgbà Ìdẹ̀ra).
Verse 113
مَا كَانَ لِلنَّبِىِّ وَٱلَّذِينَ ءَامَنُوٓا۟ أَن يَسْتَغْفِرُوا۟ لِلْمُشْرِكِينَ وَلَوْ كَانُوٓا۟ أُو۟لِى قُرْبَىٰ مِنۢ بَعْدِ مَا تَبَيَّنَ لَهُمْ أَنَّهُمْ أَصْحَـٰبُ ٱلْجَحِيمِ
Transliteration mā kāna lilnnabiyyi wa-alladhīna āmanū an yastaghfirū lil'mush'rikīna walaw kānū ulī qur'bā min baʿdi mā tabayyana lahum annahum aṣḥābu l-jaḥīmi
Yoruba Kò yẹ fún Ànábì àti àwọn tó gbàgbọ́ lódodo láti tọrọ àforíjìn fún àwọn ọ̀sẹbọ, wọn ìbáà jẹ́ ẹbí, lẹ́yìn tí ó ti hàn sí wọn pé dájúdájú èrò inú iná Jẹhīm ni wọ́n.
Verse 114
وَمَا كَانَ ٱسْتِغْفَارُ إِبْرَٰهِيمَ لِأَبِيهِ إِلَّا عَن مَّوْعِدَةٍ وَعَدَهَآ إِيَّاهُ فَلَمَّا تَبَيَّنَ لَهُۥٓ أَنَّهُۥ عَدُوٌّ لِّلَّهِ تَبَرَّأَ مِنْهُ ۚ إِنَّ إِبْرَٰهِيمَ لَأَوَّٰهٌ حَلِيمٌ
Transliteration wamā kāna is'tigh'fāru ib'rāhīma li-abīhi illā ʿan mawʿidatin waʿadahā iyyāhu falammā tabayyana lahu annahu ʿaduwwun lillahi tabarra-a min'hu inna ib'rāhīma la-awwāhun ḥalīmun
Yoruba Àti pé àforíjìn tí (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm tọrọ fún bàbá rẹ̀ kò sì jẹ́ kiní kan bí kò ṣe nítorí àdéhùn tó ṣe fún un. Ṣùgbọ́n nígbà tí ó hàn sí i pé dájúdájú ọ̀tá Allāhu ni (bàbá rẹ̀), ó yọwọ́ yọsẹ̀ kúrò nínú rẹ̀. Dájúdájú (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm ni olùrawọ́rasẹ̀, olùfaradà.
Verse 115
وَمَا كَانَ ٱللَّهُ لِيُضِلَّ قَوْمًۢا بَعْدَ إِذْ هَدَىٰهُمْ حَتَّىٰ يُبَيِّنَ لَهُم مَّا يَتَّقُونَ ۚ إِنَّ ٱللَّهَ بِكُلِّ شَىْءٍ عَلِيمٌ
Transliteration wamā kāna l-lahu liyuḍilla qawman baʿda idh hadāhum ḥattā yubayyina lahum mā yattaqūna inna l-laha bikulli shayin ʿalīmun
Yoruba Allāhu kì í mú ìṣìnà bá ìjọ kan, lẹ́yìn ìgbà tí Ó ti tọ́ wọn sọ́nà, títí (Allāhu) yóò fi ṣe àlàyé n̄ǹkan tí wọ́n máa ṣọ́ra fún fún wọn. Dájúdájú Allāhu ni Onímọ̀ nípa gbogbo n̄ǹkan.1
Verse 116
إِنَّ ٱللَّهَ لَهُۥ مُلْكُ ٱلسَّمَـٰوَٰتِ وَٱلْأَرْضِ ۖ يُحْىِۦ وَيُمِيتُ ۚ وَمَا لَكُم مِّن دُونِ ٱللَّهِ مِن وَلِىٍّ وَلَا نَصِيرٍ
Transliteration inna l-laha lahu mul'ku l-samāwāti wal-arḍi yuḥ'yī wayumītu wamā lakum min dūni l-lahi min waliyyin walā naṣīrin
Yoruba Dájúdájú Allāhu ló ni ìjọba àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Ó ń sọ ẹ̀dá di alààyè. Ó sì ń sọ ẹ̀dá di òkú. Kò sì sí aláàbò àti alárànṣe kan fún yín lẹ́yìn Allāhu.
Verse 117
لَّقَد تَّابَ ٱللَّهُ عَلَى ٱلنَّبِىِّ وَٱلْمُهَـٰجِرِينَ وَٱلْأَنصَارِ ٱلَّذِينَ ٱتَّبَعُوهُ فِى سَاعَةِ ٱلْعُسْرَةِ مِنۢ بَعْدِ مَا كَادَ يَزِيغُ قُلُوبُ فَرِيقٍ مِّنْهُمْ ثُمَّ تَابَ عَلَيْهِمْ ۚ إِنَّهُۥ بِهِمْ رَءُوفٌ رَّحِيمٌ
Transliteration laqad tāba l-lahu ʿalā l-nabiyi wal-muhājirīna wal-anṣāri alladhīna ittabaʿūhu fī sāʿati l-ʿus'rati min baʿdi mā kāda yazīghu qulūbu farīqin min'hum thumma tāba ʿalayhim innahu bihim raūfun raḥīmun
Yoruba Dájúdájú Allāhu ti gba ìronúpìwàdà Ànábì, àwọn Muhājirūn àti àwọn ’Ansọ̄r, àwọn tó tẹ̀lé e ní àkókò ìṣòro lẹ́yìn tí ọkàn ìgun kan nínú wọn fẹ́ẹ̀ yí padà, (àmọ́) lẹ́yìn náà, Allāhu gba ìronúpìwàdà wọn. Dájúdájú Òun ni Aláàánú, Àṣàkẹ́-ọ̀run fún wọn.
Verse 118
وَعَلَى ٱلثَّلَـٰثَةِ ٱلَّذِينَ خُلِّفُوا۟ حَتَّىٰٓ إِذَا ضَاقَتْ عَلَيْهِمُ ٱلْأَرْضُ بِمَا رَحُبَتْ وَضَاقَتْ عَلَيْهِمْ أَنفُسُهُمْ وَظَنُّوٓا۟ أَن لَّا مَلْجَأَ مِنَ ٱللَّهِ إِلَّآ إِلَيْهِ ثُمَّ تَابَ عَلَيْهِمْ لِيَتُوبُوٓا۟ ۚ إِنَّ ٱللَّهَ هُوَ ٱلتَّوَّابُ ٱلرَّحِيمُ
Transliteration waʿalā l-thalāthati alladhīna khullifū ḥattā idhā ḍāqat ʿalayhimu l-arḍu bimā raḥubat waḍāqat ʿalayhim anfusuhum waẓannū an lā malja-a mina l-lahi illā ilayhi thumma tāba ʿalayhim liyatūbū inna l-laha huwa l-tawābu l-raḥīmu
Yoruba (Ó tún gba ìronúpìwàdà) àwọn mẹ́ta tí A so ọ̀rọ̀ gbígba ìronúpìwàdà wọn rọ̀ (nínú àwọn olùsásẹ́yìn fún ogun Tabūk. Àwọn mùsùlùmí dẹ́yẹ sí wọn) títí ilẹ̀ fi fún mọ́ wọn tòhun ti bí ó ṣe fẹjú tó. Ọ̀rọ̀ ara wọn sì ṣú ara wọn. Wọ́n sì mọ̀ (ní àmọ̀dájú) pé kò sí ibùsásí kan tí àwọn fi lè sá mọ́ Allāhu lọ́wọ́ àfi kí wọ́n sá sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀. Lẹ́yìn náà, Allāhu gba ìronúpìwàdà wọn nítorí kí wọ́n lè máa ronú pìwàdà. Dájúdájú Allāhu, Òun ni Olùgba-ìronúpìwàdà, Àṣàkẹ́-ọ̀run.
Verse 119
يَـٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُوا۟ ٱتَّقُوا۟ ٱللَّهَ وَكُونُوا۟ مَعَ ٱلصَّـٰدِقِينَ
Transliteration yāayyuhā alladhīna āmanū ittaqū l-laha wakūnū maʿa l-ṣādiqīna
Yoruba Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ bẹ̀rù Allāhu, kí ẹ sì wà pẹ̀lú àwọn olódodo.
Verse 120
مَا كَانَ لِأَهْلِ ٱلْمَدِينَةِ وَمَنْ حَوْلَهُم مِّنَ ٱلْأَعْرَابِ أَن يَتَخَلَّفُوا۟ عَن رَّسُولِ ٱللَّهِ وَلَا يَرْغَبُوا۟ بِأَنفُسِهِمْ عَن نَّفْسِهِۦ ۚ ذَٰلِكَ بِأَنَّهُمْ لَا يُصِيبُهُمْ ظَمَأٌ وَلَا نَصَبٌ وَلَا مَخْمَصَةٌ فِى سَبِيلِ ٱللَّهِ وَلَا يَطَـُٔونَ مَوْطِئًا يَغِيظُ ٱلْكُفَّارَ وَلَا يَنَالُونَ مِنْ عَدُوٍّ نَّيْلًا إِلَّا كُتِبَ لَهُم بِهِۦ عَمَلٌ صَـٰلِحٌ ۚ إِنَّ ٱللَّهَ لَا يُضِيعُ أَجْرَ ٱلْمُحْسِنِينَ
Transliteration mā kāna li-ahli l-madīnati waman ḥawlahum mina l-aʿrābi an yatakhallafū ʿan rasūli l-lahi walā yarghabū bi-anfusihim ʿan nafsihi dhālika bi-annahum lā yuṣībuhum ẓama-on walā naṣabun walā makhmaṣatun fī sabīli l-lahi walā yaṭaūna mawṭi-an yaghīẓu l-kufāra walā yanālūna min ʿaduwwin naylan illā kutiba lahum bihi ʿamalun ṣāliḥun inna l-laha lā yuḍīʿu ajra l-muḥ'sinīna
Yoruba Kò lẹ́tọ̀ọ́ fún àwọn ará ìlú Mọdīnah àti ẹni tí ó wà ní àyíká wọn nínú àwọn Lárúbáwá oko láti sá sẹ́yìn fún Òjíṣẹ́ Allāhu (nípa ogun ẹ̀sìn. Kò sì lẹ́tọ̀ọ́ fún wọn) láti fẹ́ràn ẹ̀mí ara wọn ju ẹ̀mí rẹ̀. Ìyẹn nítorí pé dájúdájú òǹgbẹ, ìnira àti ebi kan kò níí ṣẹlẹ̀ sí wọn lójú ogun ẹ̀sìn Allāhu, wọn kò sì níí tẹ ọ̀nà kan tí ń bí àwọn aláìgbàgbọ́ nínú, àti pé ọwọ́ wọn kò níí ba kiní kan lára ọ̀tá (yálà ọrọ̀ ogun tàbí ẹ̀mí wọn) àfi kí wọ́n fi kọ iṣẹ́ rere sílẹ̀ fún wọn. Dájúdájú Allāhu kò níí fi ẹ̀san àwọn olùṣe-rere ráre.
Verse 121
وَلَا يُنفِقُونَ نَفَقَةً صَغِيرَةً وَلَا كَبِيرَةً وَلَا يَقْطَعُونَ وَادِيًا إِلَّا كُتِبَ لَهُمْ لِيَجْزِيَهُمُ ٱللَّهُ أَحْسَنَ مَا كَانُوا۟ يَعْمَلُونَ
Transliteration walā yunfiqūna nafaqatan ṣaghīratan walā kabīratan walā yaqṭaʿūna wādiyan illā kutiba lahum liyajziyahumu l-lahu aḥsana mā kānū yaʿmalūna
Yoruba Wọn kò sì níí ná owó kékeré tàbí púpọ̀ (fún ogun ẹ̀sìn), tàbí kí wọ́n la àfonífojì kan kọ já àfi kí wọ́n kọ ọ́ sílẹ̀ fún wọn nítorí kí Allāhu lè san wọ́n ní ẹ̀san rere tó dára ju ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́.
Verse 122
۞ وَمَا كَانَ ٱلْمُؤْمِنُونَ لِيَنفِرُوا۟ كَآفَّةً ۚ فَلَوْلَا نَفَرَ مِن كُلِّ فِرْقَةٍ مِّنْهُمْ طَآئِفَةٌ لِّيَتَفَقَّهُوا۟ فِى ٱلدِّينِ وَلِيُنذِرُوا۟ قَوْمَهُمْ إِذَا رَجَعُوٓا۟ إِلَيْهِمْ لَعَلَّهُمْ يَحْذَرُونَ
Transliteration wamā kāna l-mu'minūna liyanfirū kāffatan falawlā nafara min kulli fir'qatin min'hum ṭāifatun liyatafaqqahū fī l-dīni waliyundhirū qawmahum idhā rajaʿū ilayhim laʿallahum yaḥdharūna
Yoruba Àwọn mùsùlùmí kò ní láti tú jáde tán nílé pátápátá. Èé ṣe tí igun kan nínú wọn nínú ikọ̀ kọ̀ọ̀kan kò fi jáde láti wá àgbọ́yé ìmọ̀ nípa ẹ̀sìn, kí wọ́n sì máa ṣe ìkìlọ̀ fún àwọn ènìyàn wọn nígbà tí wọ́n bá padà sọ́dọ̀ wọn nítorí kí wọ́n lè ṣọ́ra ṣe.
Verse 123
يَـٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُوا۟ قَـٰتِلُوا۟ ٱلَّذِينَ يَلُونَكُم مِّنَ ٱلْكُفَّارِ وَلْيَجِدُوا۟ فِيكُمْ غِلْظَةً ۚ وَٱعْلَمُوٓا۟ أَنَّ ٱللَّهَ مَعَ ٱلْمُتَّقِينَ
Transliteration yāayyuhā alladhīna āmanū qātilū alladhīna yalūnakum mina l-kufāri walyajidū fīkum ghil'ẓatan wa-iʿ'lamū anna l-laha maʿa l-mutaqīna
Yoruba Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ gbógun ti àwọn tó súnmọ́ yín nínú àwọn aláìgbàgbọ́; kí wọ́n rí ìlekoko lára yín. Kí ẹ sì mọ̀ pé dájúdájú Allāhu wà pẹ̀lú àwọn olùbẹ̀rù (Rẹ̀).
Verse 124
وَإِذَا مَآ أُنزِلَتْ سُورَةٌ فَمِنْهُم مَّن يَقُولُ أَيُّكُمْ زَادَتْهُ هَـٰذِهِۦٓ إِيمَـٰنًا ۚ فَأَمَّا ٱلَّذِينَ ءَامَنُوا۟ فَزَادَتْهُمْ إِيمَـٰنًا وَهُمْ يَسْتَبْشِرُونَ
Transliteration wa-idhā mā unzilat sūratun famin'hum man yaqūlu ayyukum zādathu hādhihi īmānan fa-ammā alladhīna āmanū fazādathum īmānan wahum yastabshirūna
Yoruba Nígbà tí A bá sì sọ sūrah kan kalẹ̀, ó ń bẹ nínú wọn ẹni tí ó máa wí pé: “Èwo nínú yín ni èyí lé ìgbàgbọ́ (rẹ̀) kún?” Ní ti àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo, (āyah náà) yóò lé ìgbàgbọ́ (wọn) kún. Wọn yó sì máa dunnú.
Verse 125
وَأَمَّا ٱلَّذِينَ فِى قُلُوبِهِم مَّرَضٌ فَزَادَتْهُمْ رِجْسًا إِلَىٰ رِجْسِهِمْ وَمَاتُوا۟ وَهُمْ كَـٰفِرُونَ
Transliteration wa-ammā alladhīna fī qulūbihim maraḍun fazādathum rij'san ilā rij'sihim wamātū wahum kāfirūna
Yoruba Ní ti àwọn tí àìsàn kan wà nínú ọkàn wọn, (āyah náà) yó sì ṣe àlékún ẹ̀gbin sí ẹ̀gbin wọn. Wọn yó sì kú sí ipò aláìgbàgbọ́.
Verse 126
أَوَلَا يَرَوْنَ أَنَّهُمْ يُفْتَنُونَ فِى كُلِّ عَامٍ مَّرَّةً أَوْ مَرَّتَيْنِ ثُمَّ لَا يَتُوبُونَ وَلَا هُمْ يَذَّكَّرُونَ
Transliteration awalā yarawna annahum yuf'tanūna fī kulli ʿāmin marratan aw marratayni thumma lā yatūbūna walā hum yadhakkarūna
Yoruba Ṣé wọn kò rí i pé wọ́n ń dán wọn wò ní ẹ̀ẹ̀ kan tàbí ẹ̀ẹ̀ méjì ní ọdọọdún. Lẹ́yìn náà, wọn kò ronú pìwàdà, wọn kò sì lo ìrántí.
Verse 127
وَإِذَا مَآ أُنزِلَتْ سُورَةٌ نَّظَرَ بَعْضُهُمْ إِلَىٰ بَعْضٍ هَلْ يَرَىٰكُم مِّنْ أَحَدٍ ثُمَّ ٱنصَرَفُوا۟ ۚ صَرَفَ ٱللَّهُ قُلُوبَهُم بِأَنَّهُمْ قَوْمٌ لَّا يَفْقَهُونَ
Transliteration wa-idhā mā unzilat sūratun naẓara baʿḍuhum ilā baʿḍin hal yarākum min aḥadin thumma inṣarafū ṣarafa l-lahu qulūbahum bi-annahum qawmun lā yafqahūna
Yoruba Àti pé nígbà tí A bá sọ sūrah kan kalẹ̀, apá kan wọn yóò wo apá kan lójú (wọn yó sì wí pé): “Ṣé ẹnì kan ń wò yín bí?” Lẹ́yìn náà, wọ́n máa pẹ̀yìndà. Allāhu sì pa ọkàn wọn dà (sódì) nítorí pé dájúdájú àwọn ni ìjọ kan tí kò gbọ́ àgbọ́yé.
Verse 128
لَقَدْ جَآءَكُمْ رَسُولٌ مِّنْ أَنفُسِكُمْ عَزِيزٌ عَلَيْهِ مَا عَنِتُّمْ حَرِيصٌ عَلَيْكُم بِٱلْمُؤْمِنِينَ رَءُوفٌ رَّحِيمٌ
Transliteration laqad jāakum rasūlun min anfusikum ʿazīzun ʿalayhi mā ʿanittum ḥarīṣun ʿalaykum bil-mu'minīna raūfun raḥīmun
Yoruba Dájúdájú Òjíṣẹ́ kan ti wá ba yín láti ààrin yín. Ohun tí ó máa kó wàhálà ba yín lágbára lára rẹ̀. Ó ń ṣe àkólékàn (oore) fún yín; aláàánú àti oníkẹ̀ẹ́ ni fún àwọn oní gbàgbọ́ òdodo.
Verse 129
فَإِن تَوَلَّوْا۟ فَقُلْ حَسْبِىَ ٱللَّهُ لَآ إِلَـٰهَ إِلَّا هُوَ ۖ عَلَيْهِ تَوَكَّلْتُ ۖ وَهُوَ رَبُّ ٱلْعَرْشِ ٱلْعَظِيمِ
Transliteration fa-in tawallaw faqul ḥasbiya l-lahu lā ilāha illā huwa ʿalayhi tawakkaltu wahuwa rabbu l-ʿarshi l-ʿaẓīmi
Yoruba Nítorí náà, tí wọ́n bá pẹ̀yìndà, sọ pé: “Allāhu tó fún mi. Kò sí ọlọ́hun kan tí a gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo àyàfi Òun. Òun ni mo gbáralé. Òun sì ni Olúwa Ìtẹ́ ńlá.
Read Surah At-Tawbah in another language
- English (word by word)
- Albanian
- Amazigh
- Amharic
- Assamese
- Azerbaijani
- Bambara
- Bangla
- Bosnian
- Bulgarian
- Chechen
- Chinese
- Czech
- Dari
- Dhivehi
- Dutch
- Finnish
- French
- German
- Gujarati
- Hausa
- Hebrew
- Hindi
- Indonesian
- Italian
- Japanese
- Kannada
- Kazakh
- Khmer
- Kinyarwanda
- Korean
- Kurdish
- Luganda
- Malay
- Malayalam
- Maranao
- Marathi
- Nepali
- Norwegian
- Oromo
- Pashto
- Persian
- Polish
- Portuguese
- Romanian
- Russian
- Sindhi
- Sinhala
- Somali
- Spanish
- Swahili
- Swedish
- Tagalog
- Tajik
- Tamil
- Tatar
- Telugu
- Thai
- Turkish
- Ukrainian
- Urdu
- Uyghur
- Uzbek
- Vietnamese
- Yao
All 114 surahs in Yoruba: the Qur’an in Yoruba.
Yoruba translation: Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni, from Quran.com. Transliteration: Quran.com. Recitation: Mishary Alafasy, from EveryAyah.com. MyDugsi is a learning aid, not a replacement for a qualified teacher.