Surah An-Nur in Yoruba: translation and audio
Surah 24 · النور · The Light · 64 verses
Surah An-Nur verse by verse: the Arabic with a recitation you can repeat, the transliteration, and the Yoruba translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni. For the meaning of every word, see Surah An-Nur word by word in English.
Verse 1
سُورَةٌ أَنزَلْنَـٰهَا وَفَرَضْنَـٰهَا وَأَنزَلْنَا فِيهَآ ءَايَـٰتٍۭ بَيِّنَـٰتٍ لَّعَلَّكُمْ تَذَكَّرُونَ
Transliteration sūratun anzalnāhā wafaraḍnāhā wa-anzalnā fīhā āyātin bayyinātin laʿallakum tadhakkarūna
Yoruba (Èyí ni) Sūrah kan tí A sọ̀kalẹ̀. A ṣe ìdájọ́ inú rẹ̀ ní òfin (dandan). A sì sọ àwọn āyah tó yanjú kalẹ̀ sínú rẹ̀ nítorí kí ẹ lè lo ìrántí.
Verse 2
ٱلزَّانِيَةُ وَٱلزَّانِى فَٱجْلِدُوا۟ كُلَّ وَٰحِدٍ مِّنْهُمَا مِا۟ئَةَ جَلْدَةٍ ۖ وَلَا تَأْخُذْكُم بِهِمَا رَأْفَةٌ فِى دِينِ ٱللَّهِ إِن كُنتُمْ تُؤْمِنُونَ بِٱللَّهِ وَٱلْيَوْمِ ٱلْـَٔاخِرِ ۖ وَلْيَشْهَدْ عَذَابَهُمَا طَآئِفَةٌ مِّنَ ٱلْمُؤْمِنِينَ
Transliteration al-zāniyatu wal-zānī fa-ij'lidū kulla wāḥidin min'humā mi-ata jaldatin walā takhudh'kum bihimā rafatun fī dīni l-lahi in kuntum tu'minūna bil-lahi wal-yawmi l-ākhiri walyashhad ʿadhābahumā ṭāifatun mina l-mu'minīna
Yoruba Onísìná lóbìnrin àti onísìná lọ́kùnrin, ẹ na ẹnì kọ̀ọ̀kan nínú àwọn méjèèjì ní ọgọ́rùn-ún kòbókò. Ẹ má ṣe jẹ́ kí àánú wọn ṣe yín nípa ìdájọ́ Allāhu tí ẹ bá ní ìgbàgbọ́ òdodo nínú Allāhu àti Ọjọ́ Ìkẹ́yìn. Kí igun kan nínú àwọn onígbàgbọ́ òdodo sì jẹ́rìí sí ìyà àwọn méjèèjì.1
Verse 3
ٱلزَّانِى لَا يَنكِحُ إِلَّا زَانِيَةً أَوْ مُشْرِكَةً وَٱلزَّانِيَةُ لَا يَنكِحُهَآ إِلَّا زَانٍ أَوْ مُشْرِكٌ ۚ وَحُرِّمَ ذَٰلِكَ عَلَى ٱلْمُؤْمِنِينَ
Transliteration al-zānī lā yankiḥu illā zāniyatan aw mush'rikatan wal-zāniyatu lā yankiḥuhā illā zānin aw mush'rikun waḥurrima dhālika ʿalā l-mu'minīna
Yoruba Onísìná lọ́kùnrin kò níí ṣe sìná pẹ̀lú ẹnì kan bí kò ṣe onísìná lóbìnrin (ẹgbẹ́ rẹ̀) tàbí ọ̀ṣẹbọ lóbìnrin. Onísìná lóbìnrin, ẹnì kan kò níí bá a ṣe sìná bí kò ṣe onísìná lọ́kùnrin (ẹgbẹ́ rẹ̀) tàbí ọ̀ṣẹbọ lọ́kùnrin.A sì ṣe ìyẹn (sìná ṣíṣe) ní èèwọ̀ fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo.2
Verse 4
وَٱلَّذِينَ يَرْمُونَ ٱلْمُحْصَنَـٰتِ ثُمَّ لَمْ يَأْتُوا۟ بِأَرْبَعَةِ شُهَدَآءَ فَٱجْلِدُوهُمْ ثَمَـٰنِينَ جَلْدَةً وَلَا تَقْبَلُوا۟ لَهُمْ شَهَـٰدَةً أَبَدًا ۚ وَأُو۟لَـٰٓئِكَ هُمُ ٱلْفَـٰسِقُونَ
Transliteration wa-alladhīna yarmūna l-muḥ'ṣanāti thumma lam yatū bi-arbaʿati shuhadāa fa-ij'lidūhum thamānīna jaldatan walā taqbalū lahum shahādatan abadan wa-ulāika humu l-fāsiqūna
Yoruba Àwọn tó ń fi ẹ̀sùn sìná kan àwọn ọmọlúàbí lóbìnrin, lẹ́yìn náà tí wọn kò mú àwọn ẹlẹ́rìí mẹ́rin wá, ẹ nà wọ́n ní ọgọ́rin kòbókò. Ẹ má ṣe gba ẹ̀rí wọn mọ́ láéláé; àwọn wọ̀nyẹn sì ni òbìlẹ̀jẹ́.
Verse 5
إِلَّا ٱلَّذِينَ تَابُوا۟ مِنۢ بَعْدِ ذَٰلِكَ وَأَصْلَحُوا۟ فَإِنَّ ٱللَّهَ غَفُورٌ رَّحِيمٌ
Transliteration illā alladhīna tābū min baʿdi dhālika wa-aṣlaḥū fa-inna l-laha ghafūrun raḥīmun
Yoruba Àyàfi àwọn tó ronú pìwàdà lẹ́yìn ìyẹn, tí wọ́n sì ṣe àtúnṣe. Dájúdájú Allāhu ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.1
Verse 6
وَٱلَّذِينَ يَرْمُونَ أَزْوَٰجَهُمْ وَلَمْ يَكُن لَّهُمْ شُهَدَآءُ إِلَّآ أَنفُسُهُمْ فَشَهَـٰدَةُ أَحَدِهِمْ أَرْبَعُ شَهَـٰدَٰتٍۭ بِٱللَّهِ ۙ إِنَّهُۥ لَمِنَ ٱلصَّـٰدِقِينَ
Transliteration wa-alladhīna yarmūna azwājahum walam yakun lahum shuhadāu illā anfusuhum fashahādatu aḥadihim arbaʿu shahādātin bil-lahi innahu lamina l-ṣādiqīna
Yoruba Àwọn tó ń fi ẹ̀sùn sìná kan àwọn ìyàwó wọn, tí kò sì sí ẹlẹ́rìí fún wọn àfi àwọn fúnra wọn, ẹ̀rí ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn ni kí ó fi Allāhu jẹ́rìí ní ẹ̀ẹ̀ mẹrin pé dájúdájú òun wà nínú àwọn olódodo.
Verse 7
وَٱلْخَـٰمِسَةُ أَنَّ لَعْنَتَ ٱللَّهِ عَلَيْهِ إِن كَانَ مِنَ ٱلْكَـٰذِبِينَ
Transliteration wal-khāmisatu anna laʿnata l-lahi ʿalayhi in kāna mina l-kādhibīna
Yoruba Ẹ̀ẹ̀ karùn-ún sì ni pé kí ibi dandan Allāhu máa bá òun, tí òun bá wà nínú àwọn òpùrọ́.
Verse 8
وَيَدْرَؤُا۟ عَنْهَا ٱلْعَذَابَ أَن تَشْهَدَ أَرْبَعَ شَهَـٰدَٰتٍۭ بِٱللَّهِ ۙ إِنَّهُۥ لَمِنَ ٱلْكَـٰذِبِينَ
Transliteration wayadra-u ʿanhā l-ʿadhāba an tashhada arbaʿa shahādātin bil-lahi innahu lamina l-kādhibīna
Yoruba Ohun tí ó máa yẹ ìyà fún ìyàwó ni pé, kí ó fi Allāhu jẹ́rìí ní ẹ̀ẹ̀ mẹrin pé dájúdájú ọkọ òun wà nínú àwọn òpùrọ́.
Verse 9
وَٱلْخَـٰمِسَةَ أَنَّ غَضَبَ ٱللَّهِ عَلَيْهَآ إِن كَانَ مِنَ ٱلصَّـٰدِقِينَ
Transliteration wal-khāmisata anna ghaḍaba l-lahi ʿalayhā in kāna mina l-ṣādiqīna
Yoruba Ẹ̀ẹ̀ karùn-ún sì ni pé kí ìbínú Allāhu máa bá òun, tí ọkọ òun bá wà nínú àwọn olódodo.1
Verse 10
وَلَوْلَا فَضْلُ ٱللَّهِ عَلَيْكُمْ وَرَحْمَتُهُۥ وَأَنَّ ٱللَّهَ تَوَّابٌ حَكِيمٌ
Transliteration walawlā faḍlu l-lahi ʿalaykum waraḥmatuhu wa-anna l-laha tawwābun ḥakīmun
Yoruba Tí kì í bá ṣe oore àjùlọ Allāhu àti ìkẹ́ Rẹ̀ lórí yín ni (Allāhu ìbá máa tú àṣírí yín ni). Dájúdájú Allāhu ni Olùgba-ìronúpìwàdà, Ọlọ́gbọ́n.
Verse 11
إِنَّ ٱلَّذِينَ جَآءُو بِٱلْإِفْكِ عُصْبَةٌ مِّنكُمْ ۚ لَا تَحْسَبُوهُ شَرًّا لَّكُم ۖ بَلْ هُوَ خَيْرٌ لَّكُمْ ۚ لِكُلِّ ٱمْرِئٍ مِّنْهُم مَّا ٱكْتَسَبَ مِنَ ٱلْإِثْمِ ۚ وَٱلَّذِى تَوَلَّىٰ كِبْرَهُۥ مِنْهُمْ لَهُۥ عَذَابٌ عَظِيمٌ
Transliteration inna alladhīna jāū bil-if'ki ʿuṣ'batun minkum lā taḥsabūhu sharran lakum bal huwa khayrun lakum likulli im'ri-in min'hum mā ik'tasaba mina l-ith'mi wa-alladhī tawallā kib'rahu min'hum lahu ʿadhābun ʿaẓīmun
Yoruba Dájúdájú àwọn tó mú àdápa irọ́ wá jẹ́ ìjọ kan nínú yín. Ẹ má ṣe lérò pé aburú ni fún yín. Rárá o, oore ni fún yín. Ẹnì kọ̀ọ̀kan nínú wọn ti ní ohun tí ó dá ní ẹ̀ṣẹ̀. Àti pé ẹni tí ó dá (ẹ̀ṣẹ̀) jùlọ nínú wọn, ìyà ńlá ni tirẹ̀.
Verse 12
لَّوْلَآ إِذْ سَمِعْتُمُوهُ ظَنَّ ٱلْمُؤْمِنُونَ وَٱلْمُؤْمِنَـٰتُ بِأَنفُسِهِمْ خَيْرًا وَقَالُوا۟ هَـٰذَآ إِفْكٌ مُّبِينٌ
Transliteration lawlā idh samiʿ'tumūhu ẓanna l-mu'minūna wal-mu'minātu bi-anfusihim khayran waqālū hādhā if'kun mubīnun
Yoruba Nígbà tí ẹ gbọ́ ọ, kí ni kò jẹ́ kí àwọn onígbàgbọ́ òdodo lọ́kùnrin àti àwọn onígbàgbọ́ òdodo lóbìnrin ro dáadáa rora wọn, kí wọ́n sì sọ pé: “Èyí ni àdápa irọ́ pọ́nńbélé.”
Verse 13
لَّوْلَا جَآءُو عَلَيْهِ بِأَرْبَعَةِ شُهَدَآءَ ۚ فَإِذْ لَمْ يَأْتُوا۟ بِٱلشُّهَدَآءِ فَأُو۟لَـٰٓئِكَ عِندَ ٱللَّهِ هُمُ ٱلْكَـٰذِبُونَ
Transliteration lawlā jāū ʿalayhi bi-arbaʿati shuhadāa fa-idh lam yatū bil-shuhadāi fa-ulāika ʿinda l-lahi humu l-kādhibūna
Yoruba Kí ni kò jẹ́ kí wọ́n mú ẹlẹ́rìí mẹ́rin wá lórí rẹ̀? Nítorí náà, nígbà tí wọn kò ti mú àwọn ẹlẹ́rìí wá, àwọn wọ̀nyẹn, àwọn ni òpùrọ́ lọ́dọ̀ Allāhu.
Verse 14
وَلَوْلَا فَضْلُ ٱللَّهِ عَلَيْكُمْ وَرَحْمَتُهُۥ فِى ٱلدُّنْيَا وَٱلْـَٔاخِرَةِ لَمَسَّكُمْ فِى مَآ أَفَضْتُمْ فِيهِ عَذَابٌ عَظِيمٌ
Transliteration walawlā faḍlu l-lahi ʿalaykum waraḥmatuhu fī l-dun'yā wal-ākhirati lamassakum fī mā afaḍtum fīhi ʿadhābun ʿaẓīmun
Yoruba Tí kì í bá ṣe ti oore àjùlọ Allāhu àti ìkẹ́ Rẹ̀ lórí yín ní ilé ayé àti ní ọ̀run ni, dájúdájú ìyà ńlá ìbá fọwọ́ bà yín nípa ohun tí ẹ̀ ń sọ kiri ní ìsọkúsọ.
Verse 15
إِذْ تَلَقَّوْنَهُۥ بِأَلْسِنَتِكُمْ وَتَقُولُونَ بِأَفْوَاهِكُم مَّا لَيْسَ لَكُم بِهِۦ عِلْمٌ وَتَحْسَبُونَهُۥ هَيِّنًا وَهُوَ عِندَ ٱللَّهِ عَظِيمٌ
Transliteration idh talaqqawnahu bi-alsinatikum wataqūlūna bi-afwāhikum mā laysa lakum bihi ʿil'mun wataḥsabūnahu hayyinan wahuwa ʿinda l-lahi ʿaẓīmun
Yoruba (Ẹ rántí) nígbà tí ẹ̀ ń gbà á (láààrin ara yín) pẹ̀lú ahọ́n yín, tí ẹ sì ń fi ẹnu yín sọ ohun tí ẹ kò nímọ̀ nípa rẹ̀; ẹ lérò pé n̄ǹkan tó fúyẹ́ ni, n̄ǹkan ńlá sì ni lọ́dọ̀ Allāhu.
Verse 16
وَلَوْلَآ إِذْ سَمِعْتُمُوهُ قُلْتُم مَّا يَكُونُ لَنَآ أَن نَّتَكَلَّمَ بِهَـٰذَا سُبْحَـٰنَكَ هَـٰذَا بُهْتَـٰنٌ عَظِيمٌ
Transliteration walawlā idh samiʿ'tumūhu qul'tum mā yakūnu lanā an natakallama bihādhā sub'ḥānaka hādhā buh'tānun ʿaẓīmun
Yoruba Nígbà tí ẹ gbọ́ ọ, kí ni kò jẹ́ kí ẹ sọ pé: “Kì í ṣe ẹ̀tọ́ fún wa pé kí á sọ èyí. Mímọ́ ni fún Ọ (Allāhu)! Èyí ni ìparọ́-mọ́ni tó tóbi.”
Verse 17
يَعِظُكُمُ ٱللَّهُ أَن تَعُودُوا۟ لِمِثْلِهِۦٓ أَبَدًا إِن كُنتُم مُّؤْمِنِينَ
Transliteration yaʿiẓukumu l-lahu an taʿūdū limith'lihi abadan in kuntum mu'minīna
Yoruba Allāhu ń ṣe wáàsí fún yín pé kí ẹ má ṣe padà síbi irú rẹ̀ mọ́ láéláé tí ẹ bá jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo.
Verse 18
وَيُبَيِّنُ ٱللَّهُ لَكُمُ ٱلْـَٔايَـٰتِ ۚ وَٱللَّهُ عَلِيمٌ حَكِيمٌ
Transliteration wayubayyinu l-lahu lakumu l-āyāti wal-lahu ʿalīmun ḥakīmun
Yoruba Allāhu ń ṣàlàyé àwọn āyah náà fún yín. Allāhu sì ni Onímọ̀, Ọlọ́gbọ́n.
Verse 19
إِنَّ ٱلَّذِينَ يُحِبُّونَ أَن تَشِيعَ ٱلْفَـٰحِشَةُ فِى ٱلَّذِينَ ءَامَنُوا۟ لَهُمْ عَذَابٌ أَلِيمٌ فِى ٱلدُّنْيَا وَٱلْـَٔاخِرَةِ ۚ وَٱللَّهُ يَعْلَمُ وَأَنتُمْ لَا تَعْلَمُونَ
Transliteration inna alladhīna yuḥibbūna an tashīʿa l-fāḥishatu fī alladhīna āmanū lahum ʿadhābun alīmun fī l-dun'yā wal-ākhirati wal-lahu yaʿlamu wa-antum lā taʿlamūna
Yoruba Dájúdájú àwọn tó nífẹ̀ẹ́ sí kí (ọ̀rọ̀) ìbàjẹ́ máa tàn kálẹ̀ nípa àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo, ìyà ẹlẹ́ta-eléro ń bẹ fún wọn ní ayé àti ní ọ̀run. Allāhu nímọ̀, ẹ̀yin kò sì nímọ̀.
Verse 20
وَلَوْلَا فَضْلُ ٱللَّهِ عَلَيْكُمْ وَرَحْمَتُهُۥ وَأَنَّ ٱللَّهَ رَءُوفٌ رَّحِيمٌ
Transliteration walawlā faḍlu l-lahi ʿalaykum waraḥmatuhu wa-anna l-laha raūfun raḥīmun
Yoruba Tí kì í bá ṣe oore àjùlọ Allāhu àti ìkẹ́ Rẹ̀ lórí yín ni (Allāhu ìbá tètè fìyà jẹ yín ni). Dájúdájú Allāhu ni Aláàánú, Àṣàkẹ́-ọ̀run.
Verse 21
۞ يَـٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُوا۟ لَا تَتَّبِعُوا۟ خُطُوَٰتِ ٱلشَّيْطَـٰنِ ۚ وَمَن يَتَّبِعْ خُطُوَٰتِ ٱلشَّيْطَـٰنِ فَإِنَّهُۥ يَأْمُرُ بِٱلْفَحْشَآءِ وَٱلْمُنكَرِ ۚ وَلَوْلَا فَضْلُ ٱللَّهِ عَلَيْكُمْ وَرَحْمَتُهُۥ مَا زَكَىٰ مِنكُم مِّنْ أَحَدٍ أَبَدًا وَلَـٰكِنَّ ٱللَّهَ يُزَكِّى مَن يَشَآءُ ۗ وَٱللَّهُ سَمِيعٌ عَلِيمٌ
Transliteration yāayyuhā alladhīna āmanū lā tattabiʿū khuṭuwāti l-shayṭāni waman yattabiʿ khuṭuwāti l-shayṭāni fa-innahu yamuru bil-faḥshāi wal-munkari walawlā faḍlu l-lahi ʿalaykum waraḥmatuhu mā zakā minkum min aḥadin abadan walākinna l-laha yuzakkī man yashāu wal-lahu samīʿun ʿalīmun
Yoruba Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ má ṣe tẹ̀lé àwọn ojú-ẹsẹ̀ Èṣù. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì tẹ̀lé àwọn ojú-ẹsẹ̀ Èṣù, dájúdájú (Èṣù) yóò pàṣẹ ìwà ìbàjẹ́ àti aburú (fún un). Tí kì í bá ṣe oore àjùlọ Allāhu àti ìkẹ́ Rẹ̀ lórí yín ni, ẹnì kan kan ìbá tí mọ́ nínú yín láéláé. Ṣùgbọ́n Allāhu ń ṣàfọ̀mọ́ ẹni tí Ó bá fẹ́. Allāhu sì ni Olùgbọ́, Onímọ̀.
Verse 22
وَلَا يَأْتَلِ أُو۟لُوا۟ ٱلْفَضْلِ مِنكُمْ وَٱلسَّعَةِ أَن يُؤْتُوٓا۟ أُو۟لِى ٱلْقُرْبَىٰ وَٱلْمَسَـٰكِينَ وَٱلْمُهَـٰجِرِينَ فِى سَبِيلِ ٱللَّهِ ۖ وَلْيَعْفُوا۟ وَلْيَصْفَحُوٓا۟ ۗ أَلَا تُحِبُّونَ أَن يَغْفِرَ ٱللَّهُ لَكُمْ ۗ وَٱللَّهُ غَفُورٌ رَّحِيمٌ
Transliteration walā yatali ulū l-faḍli minkum wal-saʿati an yu'tū ulī l-qur'bā wal-masākīna wal-muhājirīna fī sabīli l-lahi walyaʿfū walyaṣfaḥū alā tuḥibbūna an yaghfira l-lahu lakum wal-lahu ghafūrun raḥīmun
Yoruba Kí àwọn tó ní ọlá àti ọrọ̀ púpọ̀ nínú yín má ṣe búra pé àwọn kò níí ṣe dáadáa sí àwọn ìbátan, àwọn mẹ̀kúnnù àti àwọn tó gbé ìlú wọn jù sílẹ̀ nítorí ẹ̀sìn Allāhu. Kí wọ́n ṣàforíjìn, kí wọ́n sì ṣàmójúkúrò. Ṣé ẹ kò fẹ́ kí Allāhu foríjìn yín ni? Allāhu sì ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.
Verse 23
إِنَّ ٱلَّذِينَ يَرْمُونَ ٱلْمُحْصَنَـٰتِ ٱلْغَـٰفِلَـٰتِ ٱلْمُؤْمِنَـٰتِ لُعِنُوا۟ فِى ٱلدُّنْيَا وَٱلْـَٔاخِرَةِ وَلَهُمْ عَذَابٌ عَظِيمٌ
Transliteration inna alladhīna yarmūna l-muḥ'ṣanāti l-ghāfilāti l-mu'mināti luʿinū fī l-dun'yā wal-ākhirati walahum ʿadhābun ʿaẓīmun
Yoruba Dájúdájú àwọn tó ń parọ́ sìná mọ́ àwọn ọmọlúàbí lóbìnrin, àwọn tí sìná kò sí lórí ọkàn wọn, àwọn onígbàgbọ́ òdodo lóbìnrin, A ti ṣẹ́bilé wọn ní ayé àti ní ọ̀run. Ìyà ńlá sì wà fún wọn.
Verse 24
يَوْمَ تَشْهَدُ عَلَيْهِمْ أَلْسِنَتُهُمْ وَأَيْدِيهِمْ وَأَرْجُلُهُم بِمَا كَانُوا۟ يَعْمَلُونَ
Transliteration yawma tashhadu ʿalayhim alsinatuhum wa-aydīhim wa-arjuluhum bimā kānū yaʿmalūna
Yoruba Ní ọjọ́ tí àwọn ahọ́n wọn, ọwọ́ wọn àti ẹsẹ̀ wọn yóò máa jẹ́rìí takò wọ́n nípa ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́,
Verse 25
يَوْمَئِذٍ يُوَفِّيهِمُ ٱللَّهُ دِينَهُمُ ٱلْحَقَّ وَيَعْلَمُونَ أَنَّ ٱللَّهَ هُوَ ٱلْحَقُّ ٱلْمُبِينُ
Transliteration yawma-idhin yuwaffīhimu l-lahu dīnahumu l-ḥaqa wayaʿlamūna anna l-laha huwa l-ḥaqu l-mubīnu
Yoruba ní ọjọ́ yẹn ni Allāhu yóò san wọ́n ní ẹ̀san wọn tí ó tọ́ sí wọn. Wọn yó sì mọ̀ pé dájúdájú Allāhu, Òun ni Òdodo pọ́nńbélé.
Verse 26
ٱلْخَبِيثَـٰتُ لِلْخَبِيثِينَ وَٱلْخَبِيثُونَ لِلْخَبِيثَـٰتِ ۖ وَٱلطَّيِّبَـٰتُ لِلطَّيِّبِينَ وَٱلطَّيِّبُونَ لِلطَّيِّبَـٰتِ ۚ أُو۟لَـٰٓئِكَ مُبَرَّءُونَ مِمَّا يَقُولُونَ ۖ لَهُم مَّغْفِرَةٌ وَرِزْقٌ كَرِيمٌ
Transliteration al-khabīthātu lil'khabīthīna wal-khabīthūna lil'khabīthāti wal-ṭayibātu lilṭṭayyibīna wal-ṭayibūna lilṭṭayyibāti ulāika mubarraūna mimmā yaqūlūna lahum maghfiratun wariz'qun karīmun
Yoruba Àwọn obìnrin burúkú wà fún àwọn ọkùnrin burúkú. Àwọn ọkùnrin burúkú sì wà fún àwọn obìnrin burúkú. Àwọn obìnrin rere wà fún àwọn ọkùnrin rere. Àwọn ọkùnrin rere sì wà fún àwọn obìnrin rere.Àwọn (ẹni rere) wọ̀nyí mọ́wọ́-mọ́sẹ̀ nínú (àìdaa) tí wọ́n ń sọ sí wọn. Àforíjìn àti èsè alápọ̀n-ọ́nlé ń bẹ fún wọn.
Verse 27
يَـٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُوا۟ لَا تَدْخُلُوا۟ بُيُوتًا غَيْرَ بُيُوتِكُمْ حَتَّىٰ تَسْتَأْنِسُوا۟ وَتُسَلِّمُوا۟ عَلَىٰٓ أَهْلِهَا ۚ ذَٰلِكُمْ خَيْرٌ لَّكُمْ لَعَلَّكُمْ تَذَكَّرُونَ
Transliteration yāayyuhā alladhīna āmanū lā tadkhulū buyūtan ghayra buyūtikum ḥattā tastanisū watusallimū ʿalā ahlihā dhālikum khayrun lakum laʿallakum tadhakkarūna
Yoruba Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ má ṣe wọ àwọn ilé kan yàtọ̀ sí àwọn ilé yín títí ẹ máa fi tọrọ ìyọ̀ǹda àti (títí) ẹ máa fi sálámọ̀ sí àwọn ará inú ilé náà. Ìyẹn lóore jùlọ fún yín nítorí kí ẹ lè lo ìrántí.
Verse 28
فَإِن لَّمْ تَجِدُوا۟ فِيهَآ أَحَدًا فَلَا تَدْخُلُوهَا حَتَّىٰ يُؤْذَنَ لَكُمْ ۖ وَإِن قِيلَ لَكُمُ ٱرْجِعُوا۟ فَٱرْجِعُوا۟ ۖ هُوَ أَزْكَىٰ لَكُمْ ۚ وَٱللَّهُ بِمَا تَعْمَلُونَ عَلِيمٌ
Transliteration fa-in lam tajidū fīhā aḥadan falā tadkhulūhā ḥattā yu'dhana lakum wa-in qīla lakumu ir'jiʿū fa-ir'jiʿū huwa azkā lakum wal-lahu bimā taʿmalūna ʿalīmun
Yoruba Tí ẹ ò bá sì bá ẹnì kan kan nínú ilé náà, ẹ má ṣe wọ inú rẹ̀ títí wọn yóò fi yọ̀ǹda fún yín. Tí wọ́n bá sì sọ fún yín pé kí ẹ padà, nítorí náà ẹ padà. Òhun ló fọ̀ yín mọ́ jùlọ. Allāhu sì ni Onímọ̀ nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.
Verse 29
لَّيْسَ عَلَيْكُمْ جُنَاحٌ أَن تَدْخُلُوا۟ بُيُوتًا غَيْرَ مَسْكُونَةٍ فِيهَا مَتَـٰعٌ لَّكُمْ ۚ وَٱللَّهُ يَعْلَمُ مَا تُبْدُونَ وَمَا تَكْتُمُونَ
Transliteration laysa ʿalaykum junāḥun an tadkhulū buyūtan ghayra maskūnatin fīhā matāʿun lakum wal-lahu yaʿlamu mā tub'dūna wamā taktumūna
Yoruba Kò sí ẹ̀ṣẹ̀ fún yín láti wọ inú àwọn ilé kan tí kì í ṣe ibùgbé, tí àǹfààní wà nínú rẹ̀ fún yín Allāhu mọ ohun tí ẹ̀ ń ṣàfi hàn rẹ̀ àti ohun tí ẹ̀ ń fi pamọ́.
Verse 30
قُل لِّلْمُؤْمِنِينَ يَغُضُّوا۟ مِنْ أَبْصَـٰرِهِمْ وَيَحْفَظُوا۟ فُرُوجَهُمْ ۚ ذَٰلِكَ أَزْكَىٰ لَهُمْ ۗ إِنَّ ٱللَّهَ خَبِيرٌۢ بِمَا يَصْنَعُونَ
Transliteration qul lil'mu'minīna yaghuḍḍū min abṣārihim wayaḥfaẓū furūjahum dhālika azkā lahum inna l-laha khabīrun bimā yaṣnaʿūna
Yoruba Sọ fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo lọ́kùnrin pé kí wọ́n rẹ ojú wọn nílẹ̀, kí wọ́n sì ṣọ́ abẹ́ wọn. Ìyẹn fọ̀ wọ́n mọ́ jùlọ. Dájúdájú Allāhu ni Alámọ̀tán nípa ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́.
Verse 31
وَقُل لِّلْمُؤْمِنَـٰتِ يَغْضُضْنَ مِنْ أَبْصَـٰرِهِنَّ وَيَحْفَظْنَ فُرُوجَهُنَّ وَلَا يُبْدِينَ زِينَتَهُنَّ إِلَّا مَا ظَهَرَ مِنْهَا ۖ وَلْيَضْرِبْنَ بِخُمُرِهِنَّ عَلَىٰ جُيُوبِهِنَّ ۖ وَلَا يُبْدِينَ زِينَتَهُنَّ إِلَّا لِبُعُولَتِهِنَّ أَوْ ءَابَآئِهِنَّ أَوْ ءَابَآءِ بُعُولَتِهِنَّ أَوْ أَبْنَآئِهِنَّ أَوْ أَبْنَآءِ بُعُولَتِهِنَّ أَوْ إِخْوَٰنِهِنَّ أَوْ بَنِىٓ إِخْوَٰنِهِنَّ أَوْ بَنِىٓ أَخَوَٰتِهِنَّ أَوْ نِسَآئِهِنَّ أَوْ مَا مَلَكَتْ أَيْمَـٰنُهُنَّ أَوِ ٱلتَّـٰبِعِينَ غَيْرِ أُو۟لِى ٱلْإِرْبَةِ مِنَ ٱلرِّجَالِ أَوِ ٱلطِّفْلِ ٱلَّذِينَ لَمْ يَظْهَرُوا۟ عَلَىٰ عَوْرَٰتِ ٱلنِّسَآءِ ۖ وَلَا يَضْرِبْنَ بِأَرْجُلِهِنَّ لِيُعْلَمَ مَا يُخْفِينَ مِن زِينَتِهِنَّ ۚ وَتُوبُوٓا۟ إِلَى ٱللَّهِ جَمِيعًا أَيُّهَ ٱلْمُؤْمِنُونَ لَعَلَّكُمْ تُفْلِحُونَ
Transliteration waqul lil'mu'mināti yaghḍuḍ'na min abṣārihinna wayaḥfaẓna furūjahunna walā yub'dīna zīnatahunna illā mā ẓahara min'hā walyaḍrib'na bikhumurihinna ʿalā juyūbihinna walā yub'dīna zīnatahunna illā libuʿūlatihinna aw ābāihinna aw ābāi buʿūlatihinna aw abnāihinna aw abnāi buʿūlatihinna aw ikh'wānihinna aw banī ikh'wānihinna aw banī akhawātihinna aw nisāihinna aw mā malakat aymānuhunna awi l-tābiʿīna ghayri ulī l-ir'bati mina l-rijāli awi l-ṭif'li alladhīna lam yaẓharū ʿalā ʿawrāti l-nisāi walā yaḍrib'na bi-arjulihinna liyuʿ'lama mā yukh'fīna min zīnatihinna watūbū ilā l-lahi jamīʿan ayyuha l-mu'minūna laʿallakum tuf'liḥūna
Yoruba Sọ fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo lóbìnrin pé kí wọ́n rẹ ojú wọn nílẹ̀, kí wọ́n sì ṣọ́ abẹ́ wọn. Wọn kò gbọ́dọ̀ ṣàfi hàn ọ̀ṣọ́ wọn àfi èyí tí ó bá hàn nínú rẹ̀ Kí wọ́n fi ìbòrí wọn bo igbá-àyà wọn.2 Àti pé wọn kò gbọ́dọ̀ ṣàfi hàn ọ̀ṣọ́ wọn àfi fún àwọn ọkọ wọn tàbí àwọn bàbá wọn tàbí àwọn bàbá ọkọ wọn tàbí àwọn ọmọkùnrin wọn tàbí àwọn ọmọkùnrin ọkọ wọn tàbí àwọn arákùnrin wọn tàbí àwọn ọmọkùnrin arákùnrin wọn tàbí àwọn ọmọkùnrin arábìnrin wọn tàbí àwọn obìnrin (ẹgbẹ́) wọn tàbí àwọn ẹrúkùnrin wọn tàbí àwọn tó ń tẹ̀lé obìnrin fún iṣẹ́ rírán, tí wọ́n jẹ́ ọkùnrin akúra tàbí àwọn ọmọdé tí kò dá ìhòhò àwọn obìnrin mọ̀.3 Wọn kò gbọ́dọ̀ fi ẹsẹ̀ wọn rin ìrin-kokokà nítorí kí àwọn (ènìyàn) lè mọ ohun tí wọ́n fi pamọ́ (sára) nínú ọ̀ṣọ́ wọn. Kí gbogbo yín sì ronú pìwàdà sọ́dọ̀ Allāhu, ẹ̀yin onígbàgbọ́ òdodo nítorí kí ẹ lè jèrè.4
Verse 32
وَأَنكِحُوا۟ ٱلْأَيَـٰمَىٰ مِنكُمْ وَٱلصَّـٰلِحِينَ مِنْ عِبَادِكُمْ وَإِمَآئِكُمْ ۚ إِن يَكُونُوا۟ فُقَرَآءَ يُغْنِهِمُ ٱللَّهُ مِن فَضْلِهِۦ ۗ وَٱللَّهُ وَٰسِعٌ عَلِيمٌ
Transliteration wa-ankiḥū l-ayāmā minkum wal-ṣāliḥīna min ʿibādikum wa-imāikum in yakūnū fuqarāa yugh'nihimu l-lahu min faḍlihi wal-lahu wāsiʿun ʿalīmun
Yoruba Ẹ so yìgì fún àwọn ọkùnrin tí kò ní aya àti àwọn obìnrin tí kò ní ọkọ láààrin yín, (ẹ tún so yìgì) fún àwọn ẹni rere nínú àwọn ẹrúkùnrin yín àti àwọn ẹrúbìnrin yín. Tí wọ́n bá jẹ́ aláìní, Allāhu yóò rọ̀ wọ́n lọ́rọ̀ nínú ọlá Rẹ̀. Allāhu sì ni Olùgbààye, Onímọ̀.
Verse 33
وَلْيَسْتَعْفِفِ ٱلَّذِينَ لَا يَجِدُونَ نِكَاحًا حَتَّىٰ يُغْنِيَهُمُ ٱللَّهُ مِن فَضْلِهِۦ ۗ وَٱلَّذِينَ يَبْتَغُونَ ٱلْكِتَـٰبَ مِمَّا مَلَكَتْ أَيْمَـٰنُكُمْ فَكَاتِبُوهُمْ إِنْ عَلِمْتُمْ فِيهِمْ خَيْرًا ۖ وَءَاتُوهُم مِّن مَّالِ ٱللَّهِ ٱلَّذِىٓ ءَاتَىٰكُمْ ۚ وَلَا تُكْرِهُوا۟ فَتَيَـٰتِكُمْ عَلَى ٱلْبِغَآءِ إِنْ أَرَدْنَ تَحَصُّنًا لِّتَبْتَغُوا۟ عَرَضَ ٱلْحَيَوٰةِ ٱلدُّنْيَا ۚ وَمَن يُكْرِههُّنَّ فَإِنَّ ٱللَّهَ مِنۢ بَعْدِ إِكْرَٰهِهِنَّ غَفُورٌ رَّحِيمٌ
Transliteration walyastaʿfifi alladhīna lā yajidūna nikāḥan ḥattā yugh'niyahumu l-lahu min faḍlihi wa-alladhīna yabtaghūna l-kitāba mimmā malakat aymānukum fakātibūhum in ʿalim'tum fīhim khayran waātūhum min māli l-lahi alladhī ātākum walā tuk'rihū fatayātikum ʿalā l-bighāi in aradna taḥaṣṣunan litabtaghū ʿaraḍa l-ḥayati l-dun'yā waman yuk'rihhunna fa-inna l-laha min baʿdi ik'rāhihinna ghafūrun raḥīmun
Yoruba Kí àwọn tí kò ní (ìkápá) ìgbéyàwó mú ojú wọn kúrò níbi ìṣekúṣe títí Allāhu yóò fi rọ̀ wọ́n lọ́rọ̀ nínú ọlá Rẹ̀.Àwọn tó ń wá ìwé òmìnira nínú àwọn ẹrú yín, ẹ kọ ìwé òmìnira fún wọn tí ẹ bá mọ ohun rere nípa wọn. Kí ẹ sì fún wọn nínú dúkìá Allāhu tí Ó fún yín. (Nítorí dúkìá ayé tí ẹ̀ ń wá), ẹ má ṣe jẹ àwọn ẹrúbìnrin yín nípá láti lọ ṣe sìná, tí wọ́n bá fẹ́ ṣọ́ abẹ́ wọn níbi ìṣekúṣe.2 Ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ wọ́n nípá, dájúdájú Allāhu ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run lẹ́yìn tí ẹ ti jẹ wọ́n nípá.3
Verse 34
وَلَقَدْ أَنزَلْنَآ إِلَيْكُمْ ءَايَـٰتٍ مُّبَيِّنَـٰتٍ وَمَثَلًا مِّنَ ٱلَّذِينَ خَلَوْا۟ مِن قَبْلِكُمْ وَمَوْعِظَةً لِّلْمُتَّقِينَ
Transliteration walaqad anzalnā ilaykum āyātin mubayyinātin wamathalan mina alladhīna khalaw min qablikum wamawʿiẓatan lil'muttaqīna
Yoruba Dájúdájú A ti sọ àwọn àmì tó yanjú, ìtàn àwọn tó ti lọ ṣíwájú yín àti wáàsí fún àwọn olùbẹ̀rù (Allāhu) kalẹ̀ fún yín.
Verse 35
۞ ٱللَّهُ نُورُ ٱلسَّمَـٰوَٰتِ وَٱلْأَرْضِ ۚ مَثَلُ نُورِهِۦ كَمِشْكَوٰةٍ فِيهَا مِصْبَاحٌ ۖ ٱلْمِصْبَاحُ فِى زُجَاجَةٍ ۖ ٱلزُّجَاجَةُ كَأَنَّهَا كَوْكَبٌ دُرِّىٌّ يُوقَدُ مِن شَجَرَةٍ مُّبَـٰرَكَةٍ زَيْتُونَةٍ لَّا شَرْقِيَّةٍ وَلَا غَرْبِيَّةٍ يَكَادُ زَيْتُهَا يُضِىٓءُ وَلَوْ لَمْ تَمْسَسْهُ نَارٌ ۚ نُّورٌ عَلَىٰ نُورٍ ۗ يَهْدِى ٱللَّهُ لِنُورِهِۦ مَن يَشَآءُ ۚ وَيَضْرِبُ ٱللَّهُ ٱلْأَمْثَـٰلَ لِلنَّاسِ ۗ وَٱللَّهُ بِكُلِّ شَىْءٍ عَلِيمٌ
Transliteration al-lahu nūru l-samāwāti wal-arḍi mathalu nūrihi kamish'katin fīhā miṣ'bāḥun l-miṣ'bāḥu fī zujājatin l-zujājatu ka-annahā kawkabun durriyyun yūqadu min shajaratin mubārakatin zaytūnatin lā sharqiyyatin walā gharbiyyatin yakādu zaytuhā yuḍīu walaw lam tamsashu nārun nūrun ʿalā nūrin yahdī l-lahu linūrihi man yashāu wayaḍribu l-lahu l-amthāla lilnnāsi wal-lahu bikulli shayin ʿalīmun
Yoruba Allāhu ni Olùtan-ìmọ́lẹ̀ sínú àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Àpèjúwe ìmọ́lẹ̀ Rẹ̀ dà bí òpó àtùpà kan tí àtùpà wà nínú rẹ̀. Àtùpà náà sì wà nínú díńgí. Díńgí náà dà bí ìràwọ̀ kan tó ń tàn yànrànyànràn. Wọ́n ń tan (ìmọ́lẹ̀ náà) láti ara igi ìbùkún kan, igi zaetūn, tí kò gba ìmọ́lẹ̀ ìlà òòrùn àti ìwọ̀ òòrùn (nìkan mọ).Epo rẹ̀ fẹ́rẹ̀ tànmọ́lẹ̀, iná ìbáà má dé ibẹ̀. Ìmọ́lẹ̀ lórí ìmọ́lẹ̀ ni.2 Allāhu ń tọ́ ẹnikẹ́ni tí Ó bá fẹ́ sí (ọ̀nà) ìmọ́lẹ̀ Rẹ̀. Allāhu ń fi àwọn àkàwé lélẹ̀ fún àwọn ènìyàn. Allāhu sì ni Onímọ̀ nípa gbogbo n̄ǹkan.
Verse 36
فِى بُيُوتٍ أَذِنَ ٱللَّهُ أَن تُرْفَعَ وَيُذْكَرَ فِيهَا ٱسْمُهُۥ يُسَبِّحُ لَهُۥ فِيهَا بِٱلْغُدُوِّ وَٱلْـَٔاصَالِ
Transliteration fī buyūtin adhina l-lahu an tur'faʿa wayudh'kara fīhā us'muhu yusabbiḥu lahu fīhā bil-ghuduwi wal-āṣāli
Yoruba (Àwọn àtùpà ìbùkún náà wà) nínú àwọn ilé kan (ìyẹn àwọn mọ́sálásí) èyí tí Allāhu yọ̀ǹda pé kí wọ́n gbéga,kí wọ́n sì máa dárúkọ Rẹ̀ nínú rẹ̀. (Àwọn ènìyàn) yó sì máa ṣàfọ̀mọ́ fún Un nínú rẹ̀ ní àárọ̀ àti ní ìrọ̀lẹ́;2
Verse 37
رِجَالٌ لَّا تُلْهِيهِمْ تِجَـٰرَةٌ وَلَا بَيْعٌ عَن ذِكْرِ ٱللَّهِ وَإِقَامِ ٱلصَّلَوٰةِ وَإِيتَآءِ ٱلزَّكَوٰةِ ۙ يَخَافُونَ يَوْمًا تَتَقَلَّبُ فِيهِ ٱلْقُلُوبُ وَٱلْأَبْصَـٰرُ
Transliteration rijālun lā tul'hīhim tijāratun walā bayʿun ʿan dhik'ri l-lahi wa-iqāmi l-ṣalati waītāi l-zakati yakhāfūna yawman tataqallabu fīhi l-qulūbu wal-abṣāru
Yoruba Àwọn ọkùnrin tí òwò àti kárà-kátà kò dí lọ́wọ́ níbi ìrántí Allāhu, ìrun kíkí àti Zakāh yíyọ, tí wọ́n ń páyà ọjọ́ kan tí àwọn ọkàn àti ojú yóò máa yí sí ọ̀tún yí sí òsì.
Verse 38
لِيَجْزِيَهُمُ ٱللَّهُ أَحْسَنَ مَا عَمِلُوا۟ وَيَزِيدَهُم مِّن فَضْلِهِۦ ۗ وَٱللَّهُ يَرْزُقُ مَن يَشَآءُ بِغَيْرِ حِسَابٍ
Transliteration liyajziyahumu l-lahu aḥsana mā ʿamilū wayazīdahum min faḍlihi wal-lahu yarzuqu man yashāu bighayri ḥisābin
Yoruba (Wọ́n ṣe rere wọ̀nyí) nítorí kí Allāhu lè san wọ́n ní ẹ̀san rere tó dára ju ohun tí wọ́n ṣe níṣẹ́ àti nítorí kí Ó lè ṣe àlékún fún wọn nínú oore àjùlọ Rẹ̀. Àti pé Allāhu ń pèsè ìjẹ-ìmu àti ìgbádùn fún ẹni tí Ó bá fẹ́ láì níí ní ìṣírò.1
Verse 39
وَٱلَّذِينَ كَفَرُوٓا۟ أَعْمَـٰلُهُمْ كَسَرَابٍۭ بِقِيعَةٍ يَحْسَبُهُ ٱلظَّمْـَٔانُ مَآءً حَتَّىٰٓ إِذَا جَآءَهُۥ لَمْ يَجِدْهُ شَيْـًٔا وَوَجَدَ ٱللَّهَ عِندَهُۥ فَوَفَّىٰهُ حِسَابَهُۥ ۗ وَٱللَّهُ سَرِيعُ ٱلْحِسَابِ
Transliteration wa-alladhīna kafarū aʿmāluhum kasarābin biqīʿatin yaḥsabuhu l-ẓamānu māan ḥattā idhā jāahu lam yajid'hu shayan wawajada l-laha ʿindahu fawaffāhu ḥisābahu wal-lahu sarīʿu l-ḥisābi
Yoruba Àwọn tó ṣàì gbàgbọ́, àwọn iṣẹ́ wọn dà bí ahúnpeéná tó wà ní pápá, tí ẹni tí òǹgbẹ ń gbẹ sì lérò pé omi ni títí di ìgbà tí ó dé síbẹ̀, kò sì bá n̄ǹkan kan níbẹ̀. Ó sì bá Allāhu níbi (iṣẹ́) rẹ̀ (ní ọ̀run). (Allāhu) sì ṣe àṣepé ìṣírò-iṣẹ́ rẹ̀ fún un. Allāhu ni Olùyára níbi ìṣírò-iṣẹ́.
Verse 40
أَوْ كَظُلُمَـٰتٍ فِى بَحْرٍ لُّجِّىٍّ يَغْشَىٰهُ مَوْجٌ مِّن فَوْقِهِۦ مَوْجٌ مِّن فَوْقِهِۦ سَحَابٌ ۚ ظُلُمَـٰتٌۢ بَعْضُهَا فَوْقَ بَعْضٍ إِذَآ أَخْرَجَ يَدَهُۥ لَمْ يَكَدْ يَرَىٰهَا ۗ وَمَن لَّمْ يَجْعَلِ ٱللَّهُ لَهُۥ نُورًا فَمَا لَهُۥ مِن نُّورٍ
Transliteration aw kaẓulumātin fī baḥrin lujjiyyin yaghshāhu mawjun min fawqihi mawjun min fawqihi saḥābun ẓulumātun baʿḍuhā fawqa baʿḍin idhā akhraja yadahu lam yakad yarāhā waman lam yajʿali l-lahu lahu nūran famā lahu min nūrin
Yoruba Tàbí (iṣẹ́ àwọn aláìgbàgbọ́) dà bí àwọn òkùnkùn kan nínú ibúdò jíjìn, tí ìgbì omi ń bò ó mọ́lẹ̀, tí ìgbì omi mìíràn tún wà ní òkè rẹ̀, tí ẹ̀ṣújò sì wà ní òkè rẹ̀; àwọn òkùnkùn biribiri tí apá kan wọ́n wà lórí apá kan (nìyí). Nígbà tí ó bá nawọ́ ara rẹ̀ jáde, kò ní fẹ́ẹ̀ rí i. Ẹnikẹ́ni tí Allāhu kò bá fún ní ìmọ́lẹ̀, kò lè sí ìmọ́lẹ̀ kan fún un.
Verse 41
أَلَمْ تَرَ أَنَّ ٱللَّهَ يُسَبِّحُ لَهُۥ مَن فِى ٱلسَّمَـٰوَٰتِ وَٱلْأَرْضِ وَٱلطَّيْرُ صَـٰٓفَّـٰتٍ ۖ كُلٌّ قَدْ عَلِمَ صَلَاتَهُۥ وَتَسْبِيحَهُۥ ۗ وَٱللَّهُ عَلِيمٌۢ بِمَا يَفْعَلُونَ
Transliteration alam tara anna l-laha yusabbiḥu lahu man fī l-samāwāti wal-arḍi wal-ṭayru ṣāffātin kullun qad ʿalima ṣalātahu watasbīḥahu wal-lahu ʿalīmun bimā yafʿalūna
Yoruba Ṣé o ò rí i pé dájúdájú Allāhu ni gbogbo ẹni tó ń bẹ nínú àwọn sánmọ̀ àti lórí ilẹ̀ ń ṣe àfọ̀mọ́ fún? Àwọn ẹyẹ náà (ń ṣe bẹ́ẹ̀) nígbà tí wọ́n bá ń na ìyẹ́ apá wọn? Ìkọ̀ọ̀kan wọn kúkú ti mọ bí ó ṣe máa kírun rẹ̀ àti bí ó ṣe máa ṣe àfọ̀mọ́ rẹ̀ (fún Un). Allāhu sì ni Onímọ̀ nípa ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́.
Verse 42
وَلِلَّهِ مُلْكُ ٱلسَّمَـٰوَٰتِ وَٱلْأَرْضِ ۖ وَإِلَى ٱللَّهِ ٱلْمَصِيرُ
Transliteration walillahi mul'ku l-samāwāti wal-arḍi wa-ilā l-lahi l-maṣīru
Yoruba Ti Allāhu ni ìjọba àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Ọ̀dọ̀ Allāhu sì ni àbọ̀ ẹ̀dá.
Verse 43
أَلَمْ تَرَ أَنَّ ٱللَّهَ يُزْجِى سَحَابًا ثُمَّ يُؤَلِّفُ بَيْنَهُۥ ثُمَّ يَجْعَلُهُۥ رُكَامًا فَتَرَى ٱلْوَدْقَ يَخْرُجُ مِنْ خِلَـٰلِهِۦ وَيُنَزِّلُ مِنَ ٱلسَّمَآءِ مِن جِبَالٍ فِيهَا مِنۢ بَرَدٍ فَيُصِيبُ بِهِۦ مَن يَشَآءُ وَيَصْرِفُهُۥ عَن مَّن يَشَآءُ ۖ يَكَادُ سَنَا بَرْقِهِۦ يَذْهَبُ بِٱلْأَبْصَـٰرِ
Transliteration alam tara anna l-laha yuz'jī saḥāban thumma yu-allifu baynahu thumma yajʿaluhu rukāman fatarā l-wadqa yakhruju min khilālihi wayunazzilu mina l-samāi min jibālin fīhā min baradin fayuṣību bihi man yashāu wayaṣrifuhu ʿan man yashāu yakādu sanā barqihi yadhhabu bil-abṣāri
Yoruba Ṣé ìwọ kò wòye pé dájúdájú Allāhu ń da ẹ̀ṣújò káàkiri ni? Lẹ́yìn náà Ó ń kó o jọ mọ́ra wọn. Lẹ́yìn náà, Ó ń gbé wọn gun ara wọn, nígbà náà ni o máa rí òjò tí ó máa jáde láti ààrin rẹ̀. Láti inú sánmọ̀, Ó sì ń sọ àwọn yìyín kan (tó dà bí) àwọn àpáta kalẹ̀ sí orí ilẹ̀ ayé. Ó ń mú un kọlu ẹni tí Ó bá fẹ́. Ó sì ń ṣẹ́rí rẹ̀ kúrò fún ẹni tí Ó bá fẹ́. Kíkọ yànrànyànràn mọ̀nàmọ́ná inú ẹ̀ṣújò sì fẹ́ẹ̀ lè fọ́ àwọn ojú.
Verse 44
يُقَلِّبُ ٱللَّهُ ٱلَّيْلَ وَٱلنَّهَارَ ۚ إِنَّ فِى ذَٰلِكَ لَعِبْرَةً لِّأُو۟لِى ٱلْأَبْصَـٰرِ
Transliteration yuqallibu l-lahu al-layla wal-nahāra inna fī dhālika laʿib'ratan li-ulī l-abṣāri
Yoruba Allāhu ń yí òru àti ọ̀sán padà (ìkíní kejì n wá ní tẹ̀léǹtẹ̀lé pẹ̀lú àlékún àti àdínkù). Dájúdájú àríwòye wà nínú ìyẹn fún àwọn tó ní ojú ìríran.
Verse 45
وَٱللَّهُ خَلَقَ كُلَّ دَآبَّةٍ مِّن مَّآءٍ ۖ فَمِنْهُم مَّن يَمْشِى عَلَىٰ بَطْنِهِۦ وَمِنْهُم مَّن يَمْشِى عَلَىٰ رِجْلَيْنِ وَمِنْهُم مَّن يَمْشِى عَلَىٰٓ أَرْبَعٍ ۚ يَخْلُقُ ٱللَّهُ مَا يَشَآءُ ۚ إِنَّ ٱللَّهَ عَلَىٰ كُلِّ شَىْءٍ قَدِيرٌ
Transliteration wal-lahu khalaqa kulla dābbatin min māin famin'hum man yamshī ʿalā baṭnihi wamin'hum man yamshī ʿalā rij'layni wamin'hum man yamshī ʿalā arbaʿin yakhluqu l-lahu mā yashāu inna l-laha ʿalā kulli shayin qadīrun
Yoruba Allāhu ṣẹ̀dá gbogbo abẹ̀mí láti inú omi. Ó wà nínú wọn, èyí tó ń fi àyà rẹ̀ wọ́. Ó wà nínú wọn, èyí tó ń fi ẹsẹ̀ méjì rìn. Ó sì wà nínú wọn, èyí tó ń fi mẹ́rin rìn. Allāhu ń ṣẹ̀dá ohun tí Ó bá fẹ́. Dájúdájú Allāhu ni Alágbára lórí gbogbo n̄ǹkan.
Verse 46
لَّقَدْ أَنزَلْنَآ ءَايَـٰتٍ مُّبَيِّنَـٰتٍ ۚ وَٱللَّهُ يَهْدِى مَن يَشَآءُ إِلَىٰ صِرَٰطٍ مُّسْتَقِيمٍ
Transliteration laqad anzalnā āyātin mubayyinātin wal-lahu yahdī man yashāu ilā ṣirāṭin mus'taqīmin
Yoruba Dájúdájú A ti sọ àwọn āyah tó ń yanjú ọ̀rọ̀ kalẹ̀. Allāhu sì ń tọ́ ẹnikẹ́ni tí Ó bá fẹ́ sí ọ̀nà tààrà (’Islām).
Verse 47
وَيَقُولُونَ ءَامَنَّا بِٱللَّهِ وَبِٱلرَّسُولِ وَأَطَعْنَا ثُمَّ يَتَوَلَّىٰ فَرِيقٌ مِّنْهُم مِّنۢ بَعْدِ ذَٰلِكَ ۚ وَمَآ أُو۟لَـٰٓئِكَ بِٱلْمُؤْمِنِينَ
Transliteration wayaqūlūna āmannā bil-lahi wabil-rasūli wa-aṭaʿnā thumma yatawallā farīqun min'hum min baʿdi dhālika wamā ulāika bil-mu'minīna
Yoruba Wọ́n ń wí pé: “A gbàgbọ́ nínú Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀. A sì tẹ̀lé (àṣẹ Wọn).” Lẹ́yìn náà, igun kan nínú wọn ń pẹ̀yìndà lẹ́yìn ìyẹn. Àwọn wọ̀nyẹn kì í ṣe onígbàgbọ́ òdodo.
Verse 48
وَإِذَا دُعُوٓا۟ إِلَى ٱللَّهِ وَرَسُولِهِۦ لِيَحْكُمَ بَيْنَهُمْ إِذَا فَرِيقٌ مِّنْهُم مُّعْرِضُونَ
Transliteration wa-idhā duʿū ilā l-lahi warasūlihi liyaḥkuma baynahum idhā farīqun min'hum muʿ'riḍūna
Yoruba Àti pé nígbà tí wọ́n bá pè wọ́n sí ti Allāhu àti ti Òjíṣẹ́ Rẹ̀ nítorí kí ó lè ṣèdájọ́ láààrin wọn, nígbà náà ni igun kan nínú wọn yóò máa gbúnrí.
Verse 49
وَإِن يَكُن لَّهُمُ ٱلْحَقُّ يَأْتُوٓا۟ إِلَيْهِ مُذْعِنِينَ
Transliteration wa-in yakun lahumu l-ḥaqu yatū ilayhi mudh'ʿinīna
Yoruba Tí ó bá sì jẹ́ pé àwọn ni wọ́n ni ẹ̀tọ́ (àre) ni, wọn yóò wá bá ọ ní tọkàn-tara.
Verse 50
أَفِى قُلُوبِهِم مَّرَضٌ أَمِ ٱرْتَابُوٓا۟ أَمْ يَخَافُونَ أَن يَحِيفَ ٱللَّهُ عَلَيْهِمْ وَرَسُولُهُۥ ۚ بَلْ أُو۟لَـٰٓئِكَ هُمُ ٱلظَّـٰلِمُونَ
Transliteration afī qulūbihim maraḍun ami ir'tābū am yakhāfūna an yaḥīfa l-lahu ʿalayhim warasūluhu bal ulāika humu l-ẓālimūna
Yoruba Ṣé àrùn wà nínú ọkàn wọn ni tàbí wọ́n ṣeyèméjì? Tàbí wọ́n ń páyà pé Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀ yóò fi ẹjọ́ wọn ṣègbè ni? Rárá o. Àwọn wọ̀nyẹn, àwọn ni alábòsí.
Verse 51
إِنَّمَا كَانَ قَوْلَ ٱلْمُؤْمِنِينَ إِذَا دُعُوٓا۟ إِلَى ٱللَّهِ وَرَسُولِهِۦ لِيَحْكُمَ بَيْنَهُمْ أَن يَقُولُوا۟ سَمِعْنَا وَأَطَعْنَا ۚ وَأُو۟لَـٰٓئِكَ هُمُ ٱلْمُفْلِحُونَ
Transliteration innamā kāna qawla l-mu'minīna idhā duʿū ilā l-lahi warasūlihi liyaḥkuma baynahum an yaqūlū samiʿ'nā wa-aṭaʿnā wa-ulāika humu l-muf'liḥūna
Yoruba Ohun tí ó máa jẹ́ ọ̀rọ̀ àwọn onígbàgbọ́ òdodo nígbà tí wọ́n bá pè wọ́n sí ti Allāhu àti ti Òjíṣẹ́ Rẹ̀ nítorí kí ó lè ṣèdájọ́ láààrin wọn ni pé, wọ́n á sọ pé: “A gbọ́ (àṣẹ), a sì tẹ̀lé (àṣẹ).” Àwọn wọ̀nyẹn, àwọn ni olùjèrè.
Verse 52
وَمَن يُطِعِ ٱللَّهَ وَرَسُولَهُۥ وَيَخْشَ ٱللَّهَ وَيَتَّقْهِ فَأُو۟لَـٰٓئِكَ هُمُ ٱلْفَآئِزُونَ
Transliteration waman yuṭiʿi l-laha warasūlahu wayakhsha l-laha wayattaqhi fa-ulāika humu l-fāizūna
Yoruba Ẹnikẹ́ni tí ó bá tẹ̀lé ti Allāhu àti ti Òjíṣẹ́ Rẹ̀, tí ó ń páyà Allāhu, tí ó sì ń bẹ̀rù Rẹ̀, àwọn wọ̀nyẹn, àwọn ni olùjèrè.
Verse 53
۞ وَأَقْسَمُوا۟ بِٱللَّهِ جَهْدَ أَيْمَـٰنِهِمْ لَئِنْ أَمَرْتَهُمْ لَيَخْرُجُنَّ ۖ قُل لَّا تُقْسِمُوا۟ ۖ طَاعَةٌ مَّعْرُوفَةٌ ۚ إِنَّ ٱللَّهَ خَبِيرٌۢ بِمَا تَعْمَلُونَ
Transliteration wa-aqsamū bil-lahi jahda aymānihim la-in amartahum layakhrujunna qul lā tuq'simū ṭāʿatun maʿrūfatun inna l-laha khabīrun bimā taʿmalūna
Yoruba Wọ́n sì fi Allāhu búra tí ìbura wọn sì ní agbára pé: “Dájúdájú tí o bá pàṣẹ fún àwọn, dájúdájú àwọn yóò jáde.” Sọ pé: “Ẹ má ṣe búra mọ́. Títẹ̀lé àṣẹ (pẹ̀lú ìbúra irọ́ ẹnu yín) ti di ohun mímọ̀ (fún wa).” Dájúdájú Allāhu ni Alámọ̀tán nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.
Verse 54
قُلْ أَطِيعُوا۟ ٱللَّهَ وَأَطِيعُوا۟ ٱلرَّسُولَ ۖ فَإِن تَوَلَّوْا۟ فَإِنَّمَا عَلَيْهِ مَا حُمِّلَ وَعَلَيْكُم مَّا حُمِّلْتُمْ ۖ وَإِن تُطِيعُوهُ تَهْتَدُوا۟ ۚ وَمَا عَلَى ٱلرَّسُولِ إِلَّا ٱلْبَلَـٰغُ ٱلْمُبِينُ
Transliteration qul aṭīʿū l-laha wa-aṭīʿū l-rasūla fa-in tawallaw fa-innamā ʿalayhi mā ḥummila waʿalaykum mā ḥummil'tum wa-in tuṭīʿūhu tahtadū wamā ʿalā l-rasūli illā l-balāghu l-mubīnu
Yoruba Sọ pé: “Ẹ tẹ̀lé ti Allāhu. Kí ẹ sì tẹ̀lé ti Òjíṣẹ́ náà. Tí wọ́n bá pẹ̀yìndà, ohun tí A gbé kà á lọ́rùn ló ń bẹ lọ́rùn rẹ̀, ohun tí A sì gbé kà yín lọ́rùn ló ń bẹ lọ́rùn yín. Tí ẹ bá sì tẹ̀lé e, ẹ ti mọ̀nà tààrà. Kò sì sí ojúṣe kan fún Òjíṣẹ́ bí kò ṣe ìkéde (ẹ̀sìn) tó yanjú.”
Verse 55
وَعَدَ ٱللَّهُ ٱلَّذِينَ ءَامَنُوا۟ مِنكُمْ وَعَمِلُوا۟ ٱلصَّـٰلِحَـٰتِ لَيَسْتَخْلِفَنَّهُمْ فِى ٱلْأَرْضِ كَمَا ٱسْتَخْلَفَ ٱلَّذِينَ مِن قَبْلِهِمْ وَلَيُمَكِّنَنَّ لَهُمْ دِينَهُمُ ٱلَّذِى ٱرْتَضَىٰ لَهُمْ وَلَيُبَدِّلَنَّهُم مِّنۢ بَعْدِ خَوْفِهِمْ أَمْنًا ۚ يَعْبُدُونَنِى لَا يُشْرِكُونَ بِى شَيْـًٔا ۚ وَمَن كَفَرَ بَعْدَ ذَٰلِكَ فَأُو۟لَـٰٓئِكَ هُمُ ٱلْفَـٰسِقُونَ
Transliteration waʿada l-lahu alladhīna āmanū minkum waʿamilū l-ṣāliḥāti layastakhlifannahum fī l-arḍi kamā is'takhlafa alladhīna min qablihim walayumakkinanna lahum dīnahumu alladhī ir'taḍā lahum walayubaddilannahum min baʿdi khawfihim amnan yaʿbudūnanī lā yush'rikūna bī shayan waman kafara baʿda dhālika fa-ulāika humu l-fāsiqūna
Yoruba Allāhu ṣàdéhùn fún àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo nínú yín, tí wọ́n sì ṣe àwọn iṣẹ́ rere pé dájúdájú Ó máa fi wọ́n ṣe àrólé lórí ilẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Ó ṣe fi àwọn tó ṣíwájú wọn ṣe àrólé.Dájúdájú Ó máa fi àyè gba ẹ̀sìn wọn fún wọn, èyí tí Ó yọ́nú sí fún wọn. Lẹ́yìn ìbẹ̀rù wọn, dájúdájú Ó máa fi ìfàyàbalẹ̀ dípò rẹ̀ fún wọn. Wọ́n ń jọ́sìn fún Mi, wọn kò sì fi n̄ǹkan kan ṣẹbọ sí Mi. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì ṣàì moore lẹ́yìn ìyẹn, àwọn wọ̀nyẹn, àwọn ni òbìlẹ̀jẹ́.
Verse 56
وَأَقِيمُوا۟ ٱلصَّلَوٰةَ وَءَاتُوا۟ ٱلزَّكَوٰةَ وَأَطِيعُوا۟ ٱلرَّسُولَ لَعَلَّكُمْ تُرْحَمُونَ
Transliteration wa-aqīmū l-ṣalata waātū l-zakata wa-aṭīʿū l-rasūla laʿallakum tur'ḥamūna
Yoruba Ẹ kírun. Ẹ yọ Zakāh. Ẹ tẹ̀lé Òjíṣẹ́ náà nítorí kí A lè kẹ yín.
Verse 57
لَا تَحْسَبَنَّ ٱلَّذِينَ كَفَرُوا۟ مُعْجِزِينَ فِى ٱلْأَرْضِ ۚ وَمَأْوَىٰهُمُ ٱلنَّارُ ۖ وَلَبِئْسَ ٱلْمَصِيرُ
Transliteration lā taḥsabanna alladhīna kafarū muʿ'jizīna fī l-arḍi wamawāhumu l-nāru walabi'sa l-maṣīru
Yoruba Má ṣe lérò pé àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ mórí bọ́ nínú ìyà Allāhu lórí ilẹ̀. Iná ni ibùgbé wọn. Ìkángun náà sì burú.
Verse 58
يَـٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُوا۟ لِيَسْتَـْٔذِنكُمُ ٱلَّذِينَ مَلَكَتْ أَيْمَـٰنُكُمْ وَٱلَّذِينَ لَمْ يَبْلُغُوا۟ ٱلْحُلُمَ مِنكُمْ ثَلَـٰثَ مَرَّٰتٍ ۚ مِّن قَبْلِ صَلَوٰةِ ٱلْفَجْرِ وَحِينَ تَضَعُونَ ثِيَابَكُم مِّنَ ٱلظَّهِيرَةِ وَمِنۢ بَعْدِ صَلَوٰةِ ٱلْعِشَآءِ ۚ ثَلَـٰثُ عَوْرَٰتٍ لَّكُمْ ۚ لَيْسَ عَلَيْكُمْ وَلَا عَلَيْهِمْ جُنَاحٌۢ بَعْدَهُنَّ ۚ طَوَّٰفُونَ عَلَيْكُم بَعْضُكُمْ عَلَىٰ بَعْضٍ ۚ كَذَٰلِكَ يُبَيِّنُ ٱللَّهُ لَكُمُ ٱلْـَٔايَـٰتِ ۗ وَٱللَّهُ عَلِيمٌ حَكِيمٌ
Transliteration yāayyuhā alladhīna āmanū liyastadhinkumu alladhīna malakat aymānukum wa-alladhīna lam yablughū l-ḥuluma minkum thalātha marrātin min qabli ṣalati l-fajri waḥīna taḍaʿūna thiyābakum mina l-ẓahīrati wamin baʿdi ṣalati l-ʿishāi thalāthu ʿawrātin lakum laysa ʿalaykum walā ʿalayhim junāḥun baʿdahunna ṭawwāfūna ʿalaykum baʿḍukum ʿalā baʿḍin kadhālika yubayyinu l-lahu lakumu l-āyāti wal-lahu ʿalīmun ḥakīmun
Yoruba Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, kí àwọn ẹrú yín àti àwọn tí kò tí ì bàlágà nínú yín máa gba ìyọ̀ǹda lọ́dọ̀ yín nígbà mẹ́ta (wọ̀nyí): ṣíwájú ìrun Subh, nígbà tí ẹ bá ń bọ́ aṣọ yín sílẹ̀ fún òòrùn ọ̀sán àti lẹ́yìn ìrun alẹ́. (Ìgbà) mẹ́ta fún ìbọ́rasílẹ̀ yín (nìyí). Kò sí ẹ̀ṣẹ̀ fún ẹ̀yin àti àwọn lẹ́yìn (àsìkò) náà pé kí wọ́n wọlé tọ̀ yín; kí apá kan yín wọlé tọ apá kan. Báyẹn ni Allāhu ṣe ń ṣàlàyé àwọn āyah náà fún yín. Allāhu sì ni Onímọ̀, Ọlọ́gbọ́n.
Verse 59
وَإِذَا بَلَغَ ٱلْأَطْفَـٰلُ مِنكُمُ ٱلْحُلُمَ فَلْيَسْتَـْٔذِنُوا۟ كَمَا ٱسْتَـْٔذَنَ ٱلَّذِينَ مِن قَبْلِهِمْ ۚ كَذَٰلِكَ يُبَيِّنُ ٱللَّهُ لَكُمْ ءَايَـٰتِهِۦ ۗ وَٱللَّهُ عَلِيمٌ حَكِيمٌ
Transliteration wa-idhā balagha l-aṭfālu minkumu l-ḥuluma falyastadhinū kamā is'tadhana alladhīna min qablihim kadhālika yubayyinu l-lahu lakum āyātihi wal-lahu ʿalīmun ḥakīmun
Yoruba Nígbà tí àwọn ọmọdé yín bá sì bàlágà kí àwọn náà máa gba ìyọ̀ǹda gẹ́gẹ́ bí àwọn tó ṣíwájú wọn ṣe gba ìyọ̀ǹda. Báyẹn ni Allāhu ṣe ń ṣàlàyé àwọn āyah Rẹ̀ fún yín. Allāhu sì ni Onímọ̀, Ọlọ́gbọ́n.
Verse 60
وَٱلْقَوَٰعِدُ مِنَ ٱلنِّسَآءِ ٱلَّـٰتِى لَا يَرْجُونَ نِكَاحًا فَلَيْسَ عَلَيْهِنَّ جُنَاحٌ أَن يَضَعْنَ ثِيَابَهُنَّ غَيْرَ مُتَبَرِّجَـٰتٍۭ بِزِينَةٍ ۖ وَأَن يَسْتَعْفِفْنَ خَيْرٌ لَّهُنَّ ۗ وَٱللَّهُ سَمِيعٌ عَلِيمٌ
Transliteration wal-qawāʿidu mina l-nisāi allātī lā yarjūna nikāḥan falaysa ʿalayhinna junāḥun an yaḍaʿna thiyābahunna ghayra mutabarrijātin bizīnatin wa-an yastaʿfif'na khayrun lahunna wal-lahu samīʿun ʿalīmun
Yoruba Àwọn tó ti dàgbà kọjá ọmọ bíbí nínú àwọn obìnrin, àwọn tí kò retí ìbálòpò oorun ìfẹ́ mọ́, kò sí ẹ̀ṣẹ̀ fún wọn láti bọ́ àwọn aṣọ jilbāb wọn sílẹ̀, tí wọn kò sì níí ṣe àfihàn ọ̀ṣọ́ kan síta. Kí wọ́n kóra wọn ní ìjánu (kí wọ́n máa wọ aṣọ jilbāb wọn lọ bẹ́ẹ̀) lóore jùlọ fún wọn. Allāhu sì ni Olùgbọ́, Onímọ̀.
Verse 61
لَّيْسَ عَلَى ٱلْأَعْمَىٰ حَرَجٌ وَلَا عَلَى ٱلْأَعْرَجِ حَرَجٌ وَلَا عَلَى ٱلْمَرِيضِ حَرَجٌ وَلَا عَلَىٰٓ أَنفُسِكُمْ أَن تَأْكُلُوا۟ مِنۢ بُيُوتِكُمْ أَوْ بُيُوتِ ءَابَآئِكُمْ أَوْ بُيُوتِ أُمَّهَـٰتِكُمْ أَوْ بُيُوتِ إِخْوَٰنِكُمْ أَوْ بُيُوتِ أَخَوَٰتِكُمْ أَوْ بُيُوتِ أَعْمَـٰمِكُمْ أَوْ بُيُوتِ عَمَّـٰتِكُمْ أَوْ بُيُوتِ أَخْوَٰلِكُمْ أَوْ بُيُوتِ خَـٰلَـٰتِكُمْ أَوْ مَا مَلَكْتُم مَّفَاتِحَهُۥٓ أَوْ صَدِيقِكُمْ ۚ لَيْسَ عَلَيْكُمْ جُنَاحٌ أَن تَأْكُلُوا۟ جَمِيعًا أَوْ أَشْتَاتًا ۚ فَإِذَا دَخَلْتُم بُيُوتًا فَسَلِّمُوا۟ عَلَىٰٓ أَنفُسِكُمْ تَحِيَّةً مِّنْ عِندِ ٱللَّهِ مُبَـٰرَكَةً طَيِّبَةً ۚ كَذَٰلِكَ يُبَيِّنُ ٱللَّهُ لَكُمُ ٱلْـَٔايَـٰتِ لَعَلَّكُمْ تَعْقِلُونَ
Transliteration laysa ʿalā l-aʿmā ḥarajun walā ʿalā l-aʿraji ḥarajun walā ʿalā l-marīḍi ḥarajun walā ʿalā anfusikum an takulū min buyūtikum aw buyūti ābāikum aw buyūti ummahātikum aw buyūti ikh'wānikum aw buyūti akhawātikum aw buyūti aʿmāmikum aw buyūti ʿammātikum aw buyūti akhwālikum aw buyūti khālātikum aw mā malaktum mafātiḥahu aw ṣadīqikum laysa ʿalaykum junāḥun an takulū jamīʿan aw ashtātan fa-idhā dakhaltum buyūtan fasallimū ʿalā anfusikum taḥiyyatan min ʿindi l-lahi mubārakatan ṭayyibatan kadhālika yubayyinu l-lahu lakumu l-āyāti laʿallakum taʿqilūna
Yoruba Kò sí ẹ̀ṣẹ̀ fún afọ́jú, kò sí ẹ̀ṣẹ̀ fún arọ, kò sí ẹ̀ṣẹ̀ fún aláìsàn, kò sì sí ẹ̀ṣẹ̀ fún ẹ̀yin náà láti jẹun nínú ilé yín, tàbí ilé àwọn bàbá yín, tàbí ilé àwọn ìyá yín, tàbí ilé àwọn arákùnrin yín, tàbí ilé àwọn arábìnrin yín, tàbí ilé àwọn arákùnrin bàbá yín, tàbí ilé àwọn arábìnrin bàbá yín, tàbí ilé àwọn arákùnrin ìyá yín, tàbí ilé àwọn arábìnrin ìyá yín, tàbí (ilé) tí ẹ ní ìkápá lórí àwọn kọ́kọ́rọ́ rẹ̀, tàbí (ilé) ọ̀rẹ́ yín. Kò sí ẹ̀ṣẹ̀ fún yín láti jẹun papọ̀ tàbí ní ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Nítorí náà, tí ẹ bá wọ àwọn inú ilé kan, ẹ sálámọ̀ síra yín. (Èyí jẹ́) ìkíni ìbùkún tó dára láti ọ̀dọ̀ Allāhu. Báyẹn ni Allāhu ṣe ń ṣàlàyé àwọn āyah náà fún yín nítorí kí ẹ lè ṣe làákàyè.
Verse 62
إِنَّمَا ٱلْمُؤْمِنُونَ ٱلَّذِينَ ءَامَنُوا۟ بِٱللَّهِ وَرَسُولِهِۦ وَإِذَا كَانُوا۟ مَعَهُۥ عَلَىٰٓ أَمْرٍ جَامِعٍ لَّمْ يَذْهَبُوا۟ حَتَّىٰ يَسْتَـْٔذِنُوهُ ۚ إِنَّ ٱلَّذِينَ يَسْتَـْٔذِنُونَكَ أُو۟لَـٰٓئِكَ ٱلَّذِينَ يُؤْمِنُونَ بِٱللَّهِ وَرَسُولِهِۦ ۚ فَإِذَا ٱسْتَـْٔذَنُوكَ لِبَعْضِ شَأْنِهِمْ فَأْذَن لِّمَن شِئْتَ مِنْهُمْ وَٱسْتَغْفِرْ لَهُمُ ٱللَّهَ ۚ إِنَّ ٱللَّهَ غَفُورٌ رَّحِيمٌ
Transliteration innamā l-mu'minūna alladhīna āmanū bil-lahi warasūlihi wa-idhā kānū maʿahu ʿalā amrin jāmiʿin lam yadhhabū ḥattā yastadhinūhu inna alladhīna yastadhinūnaka ulāika alladhīna yu'minūna bil-lahi warasūlihi fa-idhā is'tadhanūka libaʿḍi shanihim fadhan liman shi'ta min'hum wa-is'taghfir lahumu l-laha inna l-laha ghafūrun raḥīmun
Yoruba Àwọn onígbàgbọ́ ni àwọn tó gbàgbọ́ nínú Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀. Nígbà tí wọ́n bá sì wà pẹ̀lú rẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ kan tí ó kan gbogbogbò, wọn kò níí lọ títí wọn yóò fi gba ìyọ̀ǹda lọ́dọ̀ rẹ̀. Dájúdájú àwọn tó ń gba ìyọ̀ǹda lọ́dọ̀ rẹ, àwọn wọ̀nyẹn ni àwọn tó gbàgbọ́ nínú Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀. Nítorí náà, tí wọ́n bá gba ìyọ̀ǹda lọ́dọ̀ rẹ fún apá kan ọ̀rọ̀ ara wọn, fún ẹni tí o bá fẹ́ ní ìyọ̀ǹda nínú wọn, kí o sì bá wọn tọrọ àforíjìn lọ́dọ̀ Allāhu. Dájúdájú Allāhu ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.
Verse 63
لَّا تَجْعَلُوا۟ دُعَآءَ ٱلرَّسُولِ بَيْنَكُمْ كَدُعَآءِ بَعْضِكُم بَعْضًا ۚ قَدْ يَعْلَمُ ٱللَّهُ ٱلَّذِينَ يَتَسَلَّلُونَ مِنكُمْ لِوَاذًا ۚ فَلْيَحْذَرِ ٱلَّذِينَ يُخَالِفُونَ عَنْ أَمْرِهِۦٓ أَن تُصِيبَهُمْ فِتْنَةٌ أَوْ يُصِيبَهُمْ عَذَابٌ أَلِيمٌ
Transliteration lā tajʿalū duʿāa l-rasūli baynakum kaduʿāi baʿḍikum baʿḍan qad yaʿlamu l-lahu alladhīna yatasallalūna minkum liwādhan falyaḥdhari alladhīna yukhālifūna ʿan amrihi an tuṣībahum fit'natun aw yuṣībahum ʿadhābun alīmun
Yoruba Ẹ má ṣe ládìsọ́kàn pé ìpè Òjíṣẹ́láààrin yín dà bí ìpè apá kan fún apá kan. Allāhu kúkú ti mọ àwọn tó ń yọ́ sá lọ nínú yín. Nítorí náà, kí àwọn tó ń yapa àṣẹ rẹ̀ ṣọ́ra nítorí kí ìdààmú má baà dé bá wọn, tàbí nítorí kí ìyà ẹlẹ́ta-eléro má baá jẹ wọ́n.
Verse 64
أَلَآ إِنَّ لِلَّهِ مَا فِى ٱلسَّمَـٰوَٰتِ وَٱلْأَرْضِ ۖ قَدْ يَعْلَمُ مَآ أَنتُمْ عَلَيْهِ وَيَوْمَ يُرْجَعُونَ إِلَيْهِ فَيُنَبِّئُهُم بِمَا عَمِلُوا۟ ۗ وَٱللَّهُ بِكُلِّ شَىْءٍ عَلِيمٌۢ
Transliteration alā inna lillahi mā fī l-samāwāti wal-arḍi qad yaʿlamu mā antum ʿalayhi wayawma yur'jaʿūna ilayhi fayunabbi-uhum bimā ʿamilū wal-lahu bikulli shayin ʿalīmun
Yoruba Gbọ́! Dájúdájú ti Allāhu ni ohunkóhun tó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Ó sì ti mọ ohun tí ẹ wà lórí rẹ̀. (Rántí) ọjọ́ tí wọn yó dá wọn padà sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀, Ó sì máa fún wọn ní ìró ohun tí wọ́n ṣe níṣẹ́. Allāhu sì ni Onímọ̀ nípa gbogbo n̄ǹkan.
Read Surah An-Nur in another language
- English (word by word)
- Albanian
- Amazigh
- Amharic
- Assamese
- Azerbaijani
- Bambara
- Bangla
- Bosnian
- Bulgarian
- Chechen
- Chinese
- Czech
- Dari
- Dhivehi
- Dutch
- Finnish
- French
- German
- Gujarati
- Hausa
- Hebrew
- Hindi
- Indonesian
- Italian
- Japanese
- Kannada
- Kazakh
- Khmer
- Kinyarwanda
- Korean
- Kurdish
- Luganda
- Malay
- Malayalam
- Maranao
- Marathi
- Nepali
- Norwegian
- Oromo
- Pashto
- Persian
- Polish
- Portuguese
- Romanian
- Russian
- Sindhi
- Sinhala
- Somali
- Spanish
- Swahili
- Swedish
- Tagalog
- Tajik
- Tamil
- Tatar
- Telugu
- Thai
- Turkish
- Ukrainian
- Urdu
- Uyghur
- Uzbek
- Vietnamese
- Yao
All 114 surahs in Yoruba: the Qur’an in Yoruba.
Yoruba translation: Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni, from Quran.com. Transliteration: Quran.com. Recitation: Mishary Alafasy, from EveryAyah.com. MyDugsi is a learning aid, not a replacement for a qualified teacher.