MyDugsiStart learning

Surah Al-Bayyinah in Yoruba: translation and audio

Surah 98 · البينة · The Clear Proof · 8 verses

Surah Al-Bayyinah verse by verse: the Arabic with a recitation you can repeat, the transliteration, and the Yoruba translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni. For the meaning of every word, see Surah Al-Bayyinah word by word in English.

Verse 1

لَمْ يَكُنِ ٱلَّذِينَ كَفَرُوا۟ مِنْ أَهْلِ ٱلْكِتَـٰبِ وَٱلْمُشْرِكِينَ مُنفَكِّينَ حَتَّىٰ تَأْتِيَهُمُ ٱلْبَيِّنَةُ

Transliteration lam yakuni alladhīna kafarū min ahli l-kitābi wal-mush'rikīna munfakkīna ḥattā tatiyahumu l-bayinatu

Yoruba Àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ nínú àwọn ahlul-kitāb àti àwọn ọ̀ṣẹbọ, wọn kò níí kúrò nínú àìgbàgbọ́ wọn títí di ìgbà tí ẹ̀rí tó yanjú yó fi máa dé ọ̀dọ̀ wọn.

Verse 2

رَسُولٌ مِّنَ ٱللَّهِ يَتْلُوا۟ صُحُفًا مُّطَهَّرَةً

Transliteration rasūlun mina l-lahi yatlū ṣuḥufan muṭahharatan

Yoruba Òjíṣẹ́ kan láti ọ̀dọ̀ Allāhu yó (sì) máa ké àwọn tákàdá mímọ́.

Verse 3

فِيهَا كُتُبٌ قَيِّمَةٌ

Transliteration fīhā kutubun qayyimatun

Yoruba Àwọn ìwé òfin tó fẹsẹ̀ rinlẹ̀ sì wà nínú rẹ̀.

Verse 4

وَمَا تَفَرَّقَ ٱلَّذِينَ أُوتُوا۟ ٱلْكِتَـٰبَ إِلَّا مِنۢ بَعْدِ مَا جَآءَتْهُمُ ٱلْبَيِّنَةُ

Transliteration wamā tafarraqa alladhīna ūtū l-kitāba illā min baʿdi mā jāathumu l-bayinatu

Yoruba Àwọn tí A fún ní tírà kò sì di ìjọ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ àfi lẹ́yìn tí ẹ̀rí tó yanjú dé bá wọn.

Verse 5

وَمَآ أُمِرُوٓا۟ إِلَّا لِيَعْبُدُوا۟ ٱللَّهَ مُخْلِصِينَ لَهُ ٱلدِّينَ حُنَفَآءَ وَيُقِيمُوا۟ ٱلصَّلَوٰةَ وَيُؤْتُوا۟ ٱلزَّكَوٰةَ ۚ وَذَٰلِكَ دِينُ ٱلْقَيِّمَةِ

Transliteration wamā umirū illā liyaʿbudū l-laha mukh'liṣīna lahu l-dīna ḥunafāa wayuqīmū l-ṣalata wayu'tū l-zakata wadhālika dīnu l-qayimati

Yoruba Àwa kò sì pa wọ́n ní àṣẹ kan bí kò ṣe pé kí wọ́n jọ́sìn fún Allāhu lẹ́ni tí yóò máa ṣe àfọ̀mọ́ ẹ̀sìn fún Un,lẹ́ni tí yóò dúró ṣinṣin nínú ẹ̀sìn.2 Kí wọ́n kírun, kí wọ́n sì yọ Zakāh. Ìyẹn sì ni ẹ̀sìn tó fẹsẹ̀ rinlẹ̀.

Verse 6

إِنَّ ٱلَّذِينَ كَفَرُوا۟ مِنْ أَهْلِ ٱلْكِتَـٰبِ وَٱلْمُشْرِكِينَ فِى نَارِ جَهَنَّمَ خَـٰلِدِينَ فِيهَآ ۚ أُو۟لَـٰٓئِكَ هُمْ شَرُّ ٱلْبَرِيَّةِ

Transliteration inna alladhīna kafarū min ahli l-kitābi wal-mush'rikīna fī nāri jahannama khālidīna fīhā ulāika hum sharru l-bariyati

Yoruba Dájúdájú àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ (wọ̀nyí) nínú àwọn ahlul-kitāb àti àwọn ọ̀ṣẹbọ, wọn yóò wà nínú Iná. Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀. Àwọn wọ̀nyẹn, àwọn ni ẹ̀dá tó burú jùlọ.

Verse 7

إِنَّ ٱلَّذِينَ ءَامَنُوا۟ وَعَمِلُوا۟ ٱلصَّـٰلِحَـٰتِ أُو۟لَـٰٓئِكَ هُمْ خَيْرُ ٱلْبَرِيَّةِ

Transliteration inna alladhīna āmanū waʿamilū l-ṣāliḥāti ulāika hum khayru l-bariyati

Yoruba Dájúdájú àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo (ìyẹn, àwọn mùsùlùmí), tí wọ́n sì ṣe àwọn iṣẹ́ rere, àwọn wọ̀nyẹn, àwọn ni ẹ̀dá tó dára jùlọ.

Verse 8

جَزَآؤُهُمْ عِندَ رَبِّهِمْ جَنَّـٰتُ عَدْنٍ تَجْرِى مِن تَحْتِهَا ٱلْأَنْهَـٰرُ خَـٰلِدِينَ فِيهَآ أَبَدًا ۖ رَّضِىَ ٱللَّهُ عَنْهُمْ وَرَضُوا۟ عَنْهُ ۚ ذَٰلِكَ لِمَنْ خَشِىَ رَبَّهُۥ

Transliteration jazāuhum ʿinda rabbihim jannātu ʿadnin tajrī min taḥtihā l-anhāru khālidīna fīhā abadan raḍiya l-lahu ʿanhum waraḍū ʿanhu dhālika liman khashiya rabbahu

Yoruba Ẹ̀san wọn ní ọ̀dọ̀ Olúwa wọn ni àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra gbére, tí àwọn odò ń ṣàn ní ìsàlẹ̀ rẹ̀. Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀ títí láéláé. Allāhu yọ́nú sí wọn. Àwọn náà yọ́nú sí (ohun tí Allāhu fún wọn). Ìyẹn wà fún ẹnikẹ́ni tí ó bá páyà Olúwa rẹ̀.

Read Surah Al-Bayyinah in another language

All languages

All 114 surahs in Yoruba: the Qur’an in Yoruba.

Learn it in MyDugsi

Yoruba translation: Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni, from Quran.com. Transliteration: Quran.com. Recitation: Mishary Alafasy, from EveryAyah.com. MyDugsi is a learning aid, not a replacement for a qualified teacher.