MyDugsiStart learning

Surah At-Tahrim in Yoruba: translation and audio

Surah 66 · التحريم · The Prohibition · 12 verses

Surah At-Tahrim verse by verse: the Arabic with a recitation you can repeat, the transliteration, and the Yoruba translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni. For the meaning of every word, see Surah At-Tahrim word by word in English.

Verse 1

يَـٰٓأَيُّهَا ٱلنَّبِىُّ لِمَ تُحَرِّمُ مَآ أَحَلَّ ٱللَّهُ لَكَ ۖ تَبْتَغِى مَرْضَاتَ أَزْوَٰجِكَ ۚ وَٱللَّهُ غَفُورٌ رَّحِيمٌ

Transliteration yāayyuhā l-nabiyu lima tuḥarrimu mā aḥalla l-lahu laka tabtaghī marḍāta azwājika wal-lahu ghafūrun raḥīmun

Yoruba Ìwọ Ànábì, nítorí kí ni o ṣe máa sọ n̄ǹkan tí Allāhu ṣe ní ẹ̀tọ́ fún ọ di èèwọ̀? Ìwọ ń wá ìyọ́nú àwọn ìyàwó rẹ. Allāhu sì ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.

Verse 2

قَدْ فَرَضَ ٱللَّهُ لَكُمْ تَحِلَّةَ أَيْمَـٰنِكُمْ ۚ وَٱللَّهُ مَوْلَىٰكُمْ ۖ وَهُوَ ٱلْعَلِيمُ ٱلْحَكِيمُ

Transliteration qad faraḍa l-lahu lakum taḥillata aymānikum wal-lahu mawlākum wahuwa l-ʿalīmu l-ḥakīmu

Yoruba Dájúdájú Allāhu ti ṣe àlàyé òfin ìtánràn ìbúra yín fún yín. Allāhu ni Olùrànlọ́wọ́ yín. Òun sì ni Onímọ̀, Ọlọ́gbọ́n.1

Verse 3

وَإِذْ أَسَرَّ ٱلنَّبِىُّ إِلَىٰ بَعْضِ أَزْوَٰجِهِۦ حَدِيثًا فَلَمَّا نَبَّأَتْ بِهِۦ وَأَظْهَرَهُ ٱللَّهُ عَلَيْهِ عَرَّفَ بَعْضَهُۥ وَأَعْرَضَ عَنۢ بَعْضٍ ۖ فَلَمَّا نَبَّأَهَا بِهِۦ قَالَتْ مَنْ أَنۢبَأَكَ هَـٰذَا ۖ قَالَ نَبَّأَنِىَ ٱلْعَلِيمُ ٱلْخَبِيرُ

Transliteration wa-idh asarra l-nabiyu ilā baʿḍi azwājihi ḥadīthan falammā nabba-at bihi wa-aẓharahu l-lahu ʿalayhi ʿarrafa baʿḍahu wa-aʿraḍa ʿan baʿḍin falammā nabba-ahā bihi qālat man anba-aka hādhā qāla nabba-aniya l-ʿalīmu l-khabīru

Yoruba Rántí nígbà tí Ànábì bá ọ̀kan nínú àwọn ìyàwó rẹ̀ s’ọ̀rọ̀ àṣírí. Nígbà tí (ẹni tó bá sọ̀rọ̀, ìyẹn Hafsọh) sì sọ̀rọ̀ náà fún (‘Ā’iṣah), Allāhu sì fi han Ànábì (pé ẹlòmíìràn ti gbọ́ sí i).Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - sì sọ apá kan rẹ̀ (fún Hafsọh pé: “O ti fi ọ̀rọ̀ Mọ̄riyah tó ‘Ā’iṣah létí.”). Ó sì fi apá kan sílẹ̀ (ìyẹn, ọ̀rọ̀ nípa ipò àrólé). Àmọ́ nígbà tí (Ànábì) fi ìró náà tó o létí, Hafsọh) sọ pé: “Ta ni ó fún ọ ní ìró èyí?” (Ànábì) sọ pé: “Onímọ̀, Alámọ̀tán l’Ó fún mi ní ìró náà.”

Verse 4

إِن تَتُوبَآ إِلَى ٱللَّهِ فَقَدْ صَغَتْ قُلُوبُكُمَا ۖ وَإِن تَظَـٰهَرَا عَلَيْهِ فَإِنَّ ٱللَّهَ هُوَ مَوْلَىٰهُ وَجِبْرِيلُ وَصَـٰلِحُ ٱلْمُؤْمِنِينَ ۖ وَٱلْمَلَـٰٓئِكَةُ بَعْدَ ذَٰلِكَ ظَهِيرٌ

Transliteration in tatūbā ilā l-lahi faqad ṣaghat qulūbukumā wa-in taẓāharā ʿalayhi fa-inna l-laha huwa mawlāhu wajib'rīlu waṣāliḥu l-mu'minīna wal-malāikatu baʿda dhālika ẓahīrun

Yoruba Tí ẹ̀yin méjèèjì bá ronú pìwàdà sí ọ̀dọ̀ Allāhu, (Ó máa gba ìronúpìwàdà yín). Ṣebí ọkàn yín kúkú ti tẹ̀ (síbi kí Ànábì má fẹ̀ẹ́ Mọ̄riyah). Tí ẹ bá sì ran ara yín lọ́wọ́ (láti kó ìbànújẹ́) bá a, dájúdájú Allāhu ni Olùrànlọ́wọ́ rẹ̀, àti (mọlāika) Jibrīl àti ẹni rere nínú àwọn onígbàgbọ́ òdodo. Lẹ́yìn ìyẹn, àwọn mọlāika tí wọ́n jẹ́ olùrànlọ́wọ́(tún wà fún un).

Verse 5

عَسَىٰ رَبُّهُۥٓ إِن طَلَّقَكُنَّ أَن يُبْدِلَهُۥٓ أَزْوَٰجًا خَيْرًا مِّنكُنَّ مُسْلِمَـٰتٍ مُّؤْمِنَـٰتٍ قَـٰنِتَـٰتٍ تَـٰٓئِبَـٰتٍ عَـٰبِدَٰتٍ سَـٰٓئِحَـٰتٍ ثَيِّبَـٰتٍ وَأَبْكَارًا

Transliteration ʿasā rabbuhu in ṭallaqakunna an yub'dilahu azwājan khayran minkunna mus'limātin mu'minātin qānitātin tāibātin ʿābidātin sāiḥātin thayyibātin wa-abkāran

Yoruba Ó ṣeé ṣe, tí ó bá kọ̀ yín sílẹ̀, kí Olúwa rẹ̀ fi àwọn obìnrin kan, tí wọn lóore jù yín lọ rọ́pò fún un, (tí wọ́n máa jẹ́) mùsùlùmí, onígbàgbọ́ òdodo, olùtẹ̀lé-àṣẹ, olùronúpìwàdà, olùjọ́sìn, olùgbààwẹ̀ (tí wọ́n máa jẹ́) adélébọ̀ àti wúńdíá.

Verse 6

يَـٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُوا۟ قُوٓا۟ أَنفُسَكُمْ وَأَهْلِيكُمْ نَارًا وَقُودُهَا ٱلنَّاسُ وَٱلْحِجَارَةُ عَلَيْهَا مَلَـٰٓئِكَةٌ غِلَاظٌ شِدَادٌ لَّا يَعْصُونَ ٱللَّهَ مَآ أَمَرَهُمْ وَيَفْعَلُونَ مَا يُؤْمَرُونَ

Transliteration yāayyuhā alladhīna āmanū qū anfusakum wa-ahlīkum nāran waqūduhā l-nāsu wal-ḥijāratu ʿalayhā malāikatun ghilāẓun shidādun lā yaʿṣūna l-laha mā amarahum wayafʿalūna mā yu'marūna

Yoruba Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ ṣọ́ ẹ̀mí ara yín àti àwọn ará ilé yín níbi Iná. Ènìyàn àti òkúta ni n̄ǹkan ìkoná rẹ̀. Àwọn mọlāika tó rorò, tí wọ́n le ni ẹ̀ṣọ́ rẹ̀. Wọn kò níí yapa àṣẹ Allāhu níbi ohun tí Ó bá pa láṣẹ fún wọn. Wọ́n sì ń ṣe ohun tí wọ́n bá pa láṣẹ fún wọn.

Verse 7

يَـٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ كَفَرُوا۟ لَا تَعْتَذِرُوا۟ ٱلْيَوْمَ ۖ إِنَّمَا تُجْزَوْنَ مَا كُنتُمْ تَعْمَلُونَ

Transliteration yāayyuhā alladhīna kafarū lā taʿtadhirū l-yawma innamā tuj'zawna mā kuntum taʿmalūna

Yoruba Ẹ̀yin tí ẹ ṣàì gbàgbọ́, ẹ má ṣe ṣàròyé ní ọjọ́ òní. Ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́ ni A óò fi san yín ní ẹ̀san.

Verse 8

يَـٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُوا۟ تُوبُوٓا۟ إِلَى ٱللَّهِ تَوْبَةً نَّصُوحًا عَسَىٰ رَبُّكُمْ أَن يُكَفِّرَ عَنكُمْ سَيِّـَٔاتِكُمْ وَيُدْخِلَكُمْ جَنَّـٰتٍ تَجْرِى مِن تَحْتِهَا ٱلْأَنْهَـٰرُ يَوْمَ لَا يُخْزِى ٱللَّهُ ٱلنَّبِىَّ وَٱلَّذِينَ ءَامَنُوا۟ مَعَهُۥ ۖ نُورُهُمْ يَسْعَىٰ بَيْنَ أَيْدِيهِمْ وَبِأَيْمَـٰنِهِمْ يَقُولُونَ رَبَّنَآ أَتْمِمْ لَنَا نُورَنَا وَٱغْفِرْ لَنَآ ۖ إِنَّكَ عَلَىٰ كُلِّ شَىْءٍ قَدِيرٌ

Transliteration yāayyuhā alladhīna āmanū tūbū ilā l-lahi tawbatan naṣūḥan ʿasā rabbukum an yukaffira ʿankum sayyiātikum wayud'khilakum jannātin tajrī min taḥtihā l-anhāru yawma lā yukh'zī l-lahu l-nabiya wa-alladhīna āmanū maʿahu nūruhum yasʿā bayna aydīhim wabi-aymānihim yaqūlūna rabbanā atmim lanā nūranā wa-igh'fir lanā innaka ʿalā kulli shayin qadīrun

Yoruba Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ ronú pìwàdà sí ọ̀dọ̀ Allāhu ní ìronúpìwàdà òdodo. Ó ṣeé ṣe pé Olúwa yín máa pa àwọn àṣìṣe yín rẹ́ fún yín. Ó sì máa mu yín wọ inú àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra tí àwọn odò ń ṣàn ní ìsàlẹ̀ rẹ̀. Ní ọjọ́ tí Allāhu kò níí dójú ti Ànábì àti àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo pẹ̀lú rẹ̀. Ìmọ́lẹ̀ wọn yóò máa tàn ní iwájú wọn àti ní ọwọ́ ọ̀tún wọn. Wọn yóò sọ pé: “Olúwa wa, pé ìmọ́lẹ̀ wa fún wa, kí O sì foríjìn wá. Dájúdájú Ìwọ ni Alágbára lórí gbogbo n̄ǹkan.”

Verse 9

يَـٰٓأَيُّهَا ٱلنَّبِىُّ جَـٰهِدِ ٱلْكُفَّارَ وَٱلْمُنَـٰفِقِينَ وَٱغْلُظْ عَلَيْهِمْ ۚ وَمَأْوَىٰهُمْ جَهَنَّمُ ۖ وَبِئْسَ ٱلْمَصِيرُ

Transliteration yāayyuhā l-nabiyu jāhidi l-kufāra wal-munāfiqīna wa-ugh'luẓ ʿalayhim wamawāhum jahannamu wabi'sa l-maṣīru

Yoruba Ìwọ Ànábì, gbógun ti àwọn aláìgbàgbọ́ àti àwọn ṣọ̀bẹ-ṣèlu mùsùlùmí. Kí o sì le mọ́ wọn. Ibùgbé wọn sì ni iná Jahanamọ. Ìkángun náà sì burú.

Verse 10

ضَرَبَ ٱللَّهُ مَثَلًا لِّلَّذِينَ كَفَرُوا۟ ٱمْرَأَتَ نُوحٍ وَٱمْرَأَتَ لُوطٍ ۖ كَانَتَا تَحْتَ عَبْدَيْنِ مِنْ عِبَادِنَا صَـٰلِحَيْنِ فَخَانَتَاهُمَا فَلَمْ يُغْنِيَا عَنْهُمَا مِنَ ٱللَّهِ شَيْـًٔا وَقِيلَ ٱدْخُلَا ٱلنَّارَ مَعَ ٱلدَّٰخِلِينَ

Transliteration ḍaraba l-lahu mathalan lilladhīna kafarū im'ra-ata nūḥin wa-im'ra-ata lūṭin kānatā taḥta ʿabdayni min ʿibādinā ṣāliḥayni fakhānatāhumā falam yugh'niyā ʿanhumā mina l-lahi shayan waqīla ud'khulā l-nāra maʿa l-dākhilīna

Yoruba Allāhu fi ìyàwó (Ànábì) Nūh àti ìyàwó (Ànábì) Lūt ṣe àpẹ̀ẹrẹ fún àwọn tó ṣàì gbàgbọ́. Àwọn méjèèjì wà lábẹ́ ẹrúsìn méjì rere nínú àwọn ẹrúsìn Wa. Àwọn (obìnrin) méjèèjì sì jàǹbá àwọn ọkọ wọn. Àwọn ọkọ wọn kò sì fi kiní kan rọ̀ wọ́n lọ́rọ̀ lọ́dọ̀ Allāhu. A ó sì sọ fún àwọn obìnrin méjèèjì pé: “Ẹ wọ inú Iná pẹ̀lú àwọn olùwọlé (sínú Iná).”

Verse 11

وَضَرَبَ ٱللَّهُ مَثَلًا لِّلَّذِينَ ءَامَنُوا۟ ٱمْرَأَتَ فِرْعَوْنَ إِذْ قَالَتْ رَبِّ ٱبْنِ لِى عِندَكَ بَيْتًا فِى ٱلْجَنَّةِ وَنَجِّنِى مِن فِرْعَوْنَ وَعَمَلِهِۦ وَنَجِّنِى مِنَ ٱلْقَوْمِ ٱلظَّـٰلِمِينَ

Transliteration waḍaraba l-lahu mathalan lilladhīna āmanū im'ra-ata fir'ʿawna idh qālat rabbi ib'ni lī ʿindaka baytan fī l-janati wanajjinī min fir'ʿawna waʿamalihi wanajjinī mina l-qawmi l-ẓālimīna

Yoruba Allāhu tún fi ìyàwó Fir‘aon ṣe àpẹ̀ẹrẹ fún àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo. Nígbà tí ó sọ pé: “Olúwa mi, kọ́ ilé kan fún mi lọ́dọ̀ Rẹ̀ nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra. Là mí lọ́wọ́ Fir‘aon àti iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀. Kí O sì là mí lọ́wọ́ ìjọ alábòsí.”

Verse 12

وَمَرْيَمَ ٱبْنَتَ عِمْرَٰنَ ٱلَّتِىٓ أَحْصَنَتْ فَرْجَهَا فَنَفَخْنَا فِيهِ مِن رُّوحِنَا وَصَدَّقَتْ بِكَلِمَـٰتِ رَبِّهَا وَكُتُبِهِۦ وَكَانَتْ مِنَ ٱلْقَـٰنِتِينَ

Transliteration wamaryama ib'nata ʿim'rāna allatī aḥṣanat farjahā fanafakhnā fīhi min rūḥinā waṣaddaqat bikalimāti rabbihā wakutubihi wakānat mina l-qānitīna

Yoruba Àti Mọryam ọmọbìnrin ‘Imrọ̄n, èyí tí ó ṣọ́ abẹ́ rẹ̀. A sì fẹ́ atẹ́gùn sí i lára nínú atẹ́gùn ẹ̀mí tí A dá. Ó gbàgbọ́ lódodo nínú àwọn ọ̀rọ̀ Olúwa rẹ̀ àti àwọn Tírà Rẹ̀. Ó sì wà nínú àwọn olùtẹ̀lé-àṣẹ Allāhu.

Read Surah At-Tahrim in another language

All languages

All 114 surahs in Yoruba: the Qur’an in Yoruba.

Learn it in MyDugsi

Yoruba translation: Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni, from Quran.com. Transliteration: Quran.com. Recitation: Mishary Alafasy, from EveryAyah.com. MyDugsi is a learning aid, not a replacement for a qualified teacher.